Categories
JẸNẸSISI

JẸNẸSISI 40

Josẹfu Túmọ̀ Àlá Àwọn Ẹlẹ́wọ̀n Meji

1 Ní àkókò kan, agbọ́tí Farao, ọba Ijipti, ati olórí alásè rẹ̀ ṣẹ ọba.

2 Inú bí Farao sí àwọn iranṣẹ rẹ̀ mejeeji yìí,

3 ó sì jù wọ́n sí ọgbà ẹ̀wọ̀n ní ilé olórí àwọn tí wọn ń ṣọ́ ààfin ninu ọgbà ẹ̀wọ̀n tí Josẹfu wà.

4 Alabojuto ọgbà ẹ̀wọ̀n náà fi wọ́n sábẹ́ àkóso Josẹfu, wọ́n sì wà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n náà fún ìgbà díẹ̀.

5 Ní òru ọjọ́ kan, agbọ́tí ọba ati olórí alásè náà lá àlá kan, àlá tí olukuluku lá sì ní ìtumọ̀ tirẹ̀.

6 Nígbà tí ilẹ̀ mọ́ tí Josẹfu rí wọn, ó rí i pé ọkàn wọn dàrú.

7 Ó bá bi wọ́n pé, “Èéṣe tí ojú yín fi rẹ̀wẹ̀sì lónìí?”

8 Wọ́n dá a lóhùn pé, “A lá àlá kan ni, a kò sì rí ẹni bá wa túmọ̀ rẹ̀.”

Josẹfu dá wọn lóhùn, ó ní, “Ṣebí Ọlọrun ni ó ni ìtumọ̀ àlá? Ẹ rọ́ àlá náà fún mi.”

9 Agbọ́tí bá rọ́ àlá tirẹ̀ fún Josẹfu, ó ní, “Mo rí ìtàkùn àjàrà kan lójú àlá.

10 Ìtàkùn náà ní ẹ̀ka mẹta, bí ewé rẹ̀ ti yọ, lẹsẹkẹsẹ, ni ó tanná, ó so, èso rẹ̀ sì pọ́n.

11 Ife Farao wà ní ọwọ́ mi, mo bá mú èso àjàrà náà, mo bẹ̀rẹ̀ sí fún un sinu ife Farao, mo sì gbé ife náà lé Farao lọ́wọ́.”

12 Josẹfu bá sọ fún un pé, “Ìtumọ̀ rẹ̀ nìyí: àwọn ẹ̀ka mẹta tí o rí dúró fún ọjọ́ mẹta.

13 Lẹ́yìn ọjọ́ mẹta Farao yóo yọ ọ́ jáde, yóo dáríjì ọ́, yóo sì fi ọ́ sí ipò rẹ pada, o óo sì tún máa gbé ọtí fún Farao bíi ti àtẹ̀yìnwá.

14 Ṣugbọn ṣá o, ranti mi nígbà tí ó bá dára fún ọ, jọ̀wọ́, ṣe mí lóore kan, ròyìn mi fún Farao, kí Farao sì yọ mí kúrò ninu àhámọ́ yìí.

15 Nítorí pé jíjí ni wọ́n jí mi gbé kúrò ní ilẹ̀ Heberu, ati pé níhìn-ín gan-an, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ tí mo ṣẹ̀ tí wọ́n fi gbé mi jù sẹ́wọ̀n yìí.”

16 Alásè rí i pé ìtumọ̀ rẹ̀ dára, ó wí fún Josẹfu pé, “Èmi náà lá àlá kan, mo ru agbọ̀n àkàrà mẹta lórí, lójú àlá.

17 Mo rí i pé oríṣìíríṣìí oúnjẹ Farao ni ó wà ninu agbọ̀n tí ó wà ní òkè patapata, mo bá tún rí i tí àwọn ẹyẹ bẹ̀rẹ̀ sí jẹ àwọn oúnjẹ yìí ní orí mi.”

18 Josẹfu dáhùn, ó ní, “Ìtumọ̀ rẹ̀ nìyí: àwọn agbọ̀n mẹta náà dúró fún ọjọ́ mẹta.

19 Lẹ́yìn ọjọ́ mẹta, Farao ọba yóo yọ ọ́ jáde níhìn-ín, yóo bẹ́ ọ lórí, yóo gbé ọ kọ́ igi, àwọn ẹyẹ yóo sì jẹ ẹran ara rẹ.”

20 Ní ọjọ́ kẹta tíí ṣe ọjọ́ ìbí Farao, ọba se àsè ńlá fún gbogbo àwọn iranṣẹ rẹ̀, ó sì mú agbọ́tí rẹ̀ ati alásè rẹ̀ jáde sí ààrin àwọn iranṣẹ rẹ̀.

21 Ó dá agbọ́tí pada sí ipò rẹ̀ láti máa gbé ọtí fún un,

22 ṣugbọn ó pàṣẹ kí wọ́n lọ so olórí alásè kọ́ igi, gẹ́gẹ́ bí Josẹfu ti túmọ̀ àlá wọn fún wọn.

23 Ṣugbọn olórí agbọ́tí kò ranti Josẹfu mọ, ó gbàgbé rẹ̀ patapata.

Categories
JẸNẸSISI

JẸNẸSISI 41

Josẹfu Túmọ̀ Àlá Ọba

1 Lẹ́yìn ọdún meji gbáko, Farao náà wá lá àlá pé òun dúró létí odò Naili.

2 Ó rí àwọn mààlúù meje kan tí wọ́n sanra rọ̀pọ̀tọ̀ rọ̀pọ̀tọ̀, tí ara wọ́n sì ń dán, wọ́n ti inú odò náà jáde wá, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí jẹ koríko létí odò.

3 Rírí tí yóo tún rí, ó rí àwọn mààlúù meje mìíràn, wọ́n tún ti inú odò náà jáde wá, àwọn wọnyi rù hangangan, wọ́n rí jàpàlà jàpàlà, wọ́n dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn meje ti àkọ́kọ́.

4 Àwọn meje tí wọ́n rù hangangan náà ki àwọn meje tí wọ́n sanra rọ̀pọ̀tọ̀ rọ̀pọ̀tọ̀ mọ́lẹ̀, wọ́n sì gbé wọn mì, Farao bá tají.

5 Ó tún sùn, ó sì lá àlá mìíràn, rírí tí yóo tún rí, ó rí ṣiiri ọkà meje lórí ẹyọ igi ọkà kan, wọ́n tóbi, wọ́n sì yọmọ.

6 Ó sì tún rí i tí ṣiiri ọkà meje mìíràn yọ lẹ́yìn wọn, wọ́n tínínrín, wọn kò sì ní ọmọ ninu rárá, nítorí afẹ́fẹ́ ìhà ìlà oòrùn ti pa ọlá mọ́ wọn lára.

7 Àwọn ṣiiri ọkà tínínrín meje náà gbé àwọn meje tí wọ́n yọmọ mì. Farao bá tún tají, ó sì tún rí i pé àlá ni òun ń lá.

8 Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, ìdààmú bá Farao, ó bá ranṣẹ lọ pe gbogbo àwọn adáhunṣe ati àwọn amòye ilẹ̀ Ijipti, ó rọ́ àlá náà fún wọn, kò sì sí ẹnìkan ninu wọn tí ó lè túmọ̀ rẹ̀ fún un.

9 Nígbà náà ni agbọ́tí sọ fún Farao pé, “Mo ranti ẹ̀ṣẹ̀ mi lónìí.

10 Nígbà tí inú fi bí ọba sí àwa iranṣẹ rẹ̀ meji, tí ọba sì gbé èmi ati alásè jù sẹ́wọ̀n ní ilé olórí àwọn tí wọn ń ṣọ́ ààfin,

11 àwa mejeeji lá àlá ní òru ọjọ́ kan náà, olukuluku àlá tí a lá ni ó sì ní ìtumọ̀.

12 Ọdọmọkunrin Heberu kan wà níbẹ̀ pẹlu wa, ó jẹ́ iranṣẹ olórí àwọn tí wọn ń ṣọ́ ààfin, nígbà tí a rọ́ àlá wa fún un, ó túmọ̀ wọn fún wa. Bí olukuluku wa ti lá àlá tirẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni ó túmọ̀ wọn.

13 Gẹ́gẹ́ bí ó ti túmọ̀ àlá wa, bẹ́ẹ̀ gan-an ni ó sì rí. Ọba dá mi pada sí ààyè mi, ó sì pàṣẹ kí wọ́n so alásè kọ́.”

14 Farao bá ranṣẹ lọ pe Josẹfu, wọ́n sì mú un jáde kúrò ninu ẹ̀wọ̀n kíá. Lẹ́yìn tí ó fá irun rẹ̀, tí ó sì pààrọ̀ aṣọ rẹ̀, ó wá siwaju Farao.

15 Farao sọ fún un pé, “Mo lá àlá kan, kò sì tíì sí ẹni tí ó lè túmọ̀ rẹ̀. Wọ́n bá sọ fún mi pé, bí o bá gbọ́ àlá, o óo lè túmọ̀ rẹ̀.”

16 Josẹfu dá Farao lóhùn, ó ní, “Kò sí ní ìkáwọ́ mi, Ọlọrun ni yóo fún kabiyesi ní ìdáhùn rere.”

17 Farao bá sọ fún Josẹfu pé, “Wò ó, lójú àlá, bí mo ti dúró létí bèbè odò Naili,

18 mo rí i tí àwọn mààlúù meje kan tí wọ́n sanra rọ̀pọ̀tọ̀ rọ̀pọ̀tọ̀, tí ara wọn sì ń dán, ti inú odò náà jáde wá, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí jẹ koríko létí odò.

19 Àwọn mààlúù meje mìíràn tún jáde láti inú odò náà, gbogbo wọn rù hangangan, wọ́n rí jàpàlà jàpàlà, n kò rí irú rẹ̀ rí ní gbogbo ilẹ̀ Ijipti.

20 Àwọn mààlúù tí wọ́n rù wọnyi gbé àwọn tí wọ́n sanra mì.

21 Nígbà tí wọ́n gbé wọn mì tán, eniyan kò lè mọ̀ rárá pé wọ́n jẹ ohunkohun, nítorí pé wọ́n tún rù hangangan bákan náà ni. Mo bá tají.

22 Mo tún lá àlá lẹẹkeji, mo rí ṣiiri ọkà meje lórí igi ọkà kan, wọ́n tóbi, wọ́n sì yọmọ.

23 Mo tún rí i tí ṣiiri ọkà meje mìíràn yọ lẹ́yìn wọn, wọ́n tínínrín, wọn kò sì ní ọmọ ninu rárá, nítorí afẹ́fẹ́ ìhà ìlà oòrùn ti pa ọlá mọ́ wọn lára.

24 Àwọn ṣiiri ọkà tí kò níláárí wọnyi gbé àwọn tí wọ́n dára mì. Mo rọ́ àwọn àlá mi fún àwọn adáhunṣe, ṣugbọn kò sí ẹnìkan tí ó lè túmọ̀ wọn fún mi.”

25 Josẹfu sọ fún Farao, ó ní, “Ọ̀kan náà ni àlá mejeeji, Ọlọrun fi ohun tí ó fẹ́ ṣe han kabiyesi ni.

26 Àwọn mààlúù rọ̀pọ̀tọ̀ rọ̀pọ̀tọ̀ meje nnì ati àwọn ṣiiri ọkà meje tí wọ́n yọmọ dúró fún ọdún meje. Ọ̀kan náà ni àwọn àlá mejeeji.

27 Àwọn mààlúù meje tí wọ́n rù, tí wọ́n sì rí jàpàlà jàpàlà tí wọ́n jáde lẹ́yìn àwọn ti àkọ́kọ́, ati àwọn ṣiiri ọkà meje tí kò yọmọ, tí afẹ́fẹ́ ìhà ìlà oòrùn ti pa ọlá mọ́ lára, àwọn náà dúró fún ìyàn ọdún meje.

28 Bí ọ̀rọ̀ ti rí gan-an ni mo sọ fún kabiyesi yìí, Ọlọrun ti fi ohun tí ó fẹ́ ṣe han kabiyesi.

29 Ọdún meje kan ń bọ̀ tí oúnjẹ yóo pọ̀ yanturu ní gbogbo ilẹ̀ Ijipti,

30 ṣugbọn lẹ́yìn náà ìyàn yóo mú fún ọdún meje, ìyàn náà yóo pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ọdún meje tí oúnjẹ pọ̀ yóo di ìgbàgbé ní ilẹ̀ Ijipti, ìyàn náà yóo run ilẹ̀ yìí.

31 Ẹnikẹ́ni kò sì ní mọ̀ pé oúnjẹ ti fi ìgbà kan pọ̀ rí, nítorí ìyàn ńlá tí yóo tẹ̀lé e yóo burú jáì.

32 Ìdí tí àlá kabiyesi náà fi jẹ́ meji ni láti fihàn pé Ọlọrun ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀, láìpẹ́, Ọlọrun yóo mú un ṣẹ.

33 “Bí ọ̀rọ̀ ti rí yìí, ó yẹ kí kabiyesi yan ọkunrin kan tí ó gbọ́n, tí ó sì lóye, kí ó fi ṣe olórí ní ilẹ̀ Ijipti.

34 Kí kabiyesi yan àwọn alabojuto ní ilẹ̀ náà kí wọ́n kó ìdámárùn-ún ìkórè ilẹ̀ Ijipti jọ láàrin ọdún meje tí ọ̀pọ̀ oúnjẹ yóo fi wà.

35 Kí wọ́n kó gbogbo oúnjẹ wọnyi jọ ninu ọdún tí oúnjẹ yóo pọ̀, kí wọ́n sì kó wọn pamọ́ sinu àwọn ìlú ńláńlá, pẹlu àṣẹ kabiyesi, kí wọ́n sì máa ṣọ́ ọ.

36 Oúnjẹ yìí ni àwọn eniyan yóo máa jẹ láàrin ọdún meje tí ìyàn yóo mú ní ilẹ̀ Ijipti, kí ilẹ̀ náà má baà parun ní àkókò ìyàn náà.”

Wọ́n fi Josẹfu Jẹ Alákòóso Ilẹ̀ Ijipti

37 Ìmọ̀ràn náà dára lójú Farao ati àwọn iranṣẹ rẹ̀.

38 Ó bá sọ fún àwọn iranṣẹ rẹ̀ pé, “Ǹjẹ́ a lè rí irú ọkunrin yìí, ẹni tí ẹ̀mí Ọlọrun ń gbé inú rẹ̀?”

39 Farao bá sọ fún Josẹfu pé, “Níwọ̀n ìgbà tí ó jẹ́ pé ìwọ ni Ọlọrun fi gbogbo nǹkan yìí hàn, kò sí ẹni tí ó gbọ́n, tí ó sì lóye bíi rẹ.

40 Ìwọ ni yóo máa ṣe olórí ilé mi, gbogbo àṣẹ tí o bá sì pa ni àwọn eniyan mi yóo tẹ̀lé, kìkì pé mo jẹ́ ọba nìkan ni n óo fi jù ọ́ lọ.”

41 Farao bá sọ fún Josẹfu pé, “Wò ó! Mo fi ọ́ ṣe alákòóso ní gbogbo ilẹ̀ Ijipti.”

42 Farao bá bọ́ òrùka èdìdì ọwọ́ rẹ̀, ó fi bọ Josẹfu lọ́wọ́, ó wọ̀ ọ́ ní aṣọ funfun olówó iyebíye, ó sì fi ẹ̀gbà wúrà sí i lọ́rùn.

43 Farao ní kí Josẹfu gun ọkọ̀ ogun rẹ̀ keji gẹ́gẹ́ bí igbákejì ọba, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí hó níwájú rẹ̀ pé, “Ẹ yàgò lọ́nà!” Bẹ́ẹ̀ ni Farao ṣe fi Josẹfu ṣe olórí, ní ilẹ̀ Ijipti.

44 Farao tún sọ fún un pé, “Èmi ni Farao, ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ ṣe ohunkohun ní ilẹ̀ Ijipti láìjẹ́ pé o fọwọ́ sí i.”

45 Lẹ́yìn náà ó sọ Josẹfu ní orúkọ Ijipti kan, orúkọ náà ni Safenati Panea, ó sì fi Asenati, ọmọ Pọtifera, fún un láti fi ṣe aya. Pọtifera yìí jẹ́ babalóòṣà oriṣa Oni, ní ìlú Heliopolisi. Josẹfu sì lọ káàkiri ilẹ̀ Ijipti.

46 Josẹfu jẹ́ ọmọ ọgbọ̀n ọdún nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lábẹ́ Farao, ọba Ijipti. A máa lọ láti ààfin ọba Farao káàkiri gbogbo ilẹ̀ Ijipti.

47 Láàrin ọdún meje tí ọ̀pọ̀ oúnjẹ wà, ilẹ̀ so èso lọpọlọpọ.

48 Josẹfu bẹ̀rẹ̀ sí kó oúnjẹ jọ fún ọdún meje tí oúnjẹ fi pọ̀ yanturu ní ilẹ̀ Ijipti, ó ń pa wọ́n mọ́ sinu àwọn ìlú ńláńlá. Gbogbo oúnjẹ tí wọ́n bá rí kójọ ní agbègbè ìlú ńlá kọ̀ọ̀kan, Josẹfu a kó o pamọ́ sinu ìlú ńlá náà.

49 Bẹ́ẹ̀ ni Josẹfu ṣe kó ọkà jọ jantirẹrẹ bíi yanrìn etí òkun. Nígbà tó yá, òun gan-an kò mọ ìwọ̀n ọkà náà mọ́, nítorí pé ó ti pọ̀ kọjá wíwọ̀n.

50 Asenati, ọmọ Pọtifera, babalóòṣà Oni, bí ọkunrin meji fún Josẹfu kí ìyàn tó bẹ̀rẹ̀.

51 Josẹfu sọ ọmọ rẹ̀ kinni ní Manase, ó ní, “Ọlọ́run ti mú mi gbàgbé gbogbo ìnira mi ati ilé baba mi.”

52 Ó sọ ọmọ keji ní Efuraimu, ó ní, “Ọlọrun ti mú mi bí sí i ní ilẹ̀ tí mo ti rí ìpọ́njú.”

53 Nígbà tí ó yá, ọdún meje tí ọ̀pọ̀ oúnjẹ wà ní Ijipti dópin.

54 Ọdún meje ìyàn sì bẹ̀rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Josẹfu ti wí, ìyàn mú ní ilẹ̀ gbogbo, ṣugbọn oúnjẹ wà ní gbogbo ilẹ̀ Ijipti.

55 Nígbà tí oúnjẹ kò sí mọ́ ní gbogbo ilẹ̀ Ijipti, àwọn eniyan náà kígbe tọ Farao lọ fún oúnjẹ. Farao sọ fún gbogbo wọn pé, “Ẹ tọ Josẹfu lọ, ohunkohun tí ó bá wí fun yín ni kí ẹ ṣe.”

56 Nígbà tí ìyàn náà tàn káàkiri gbogbo ilẹ̀, Josẹfu ṣí àwọn àká tí wọ́n kó oúnjẹ pamọ́ sí, ó ń ta oúnjẹ fún àwọn ará Ijipti, nítorí ìyàn náà mú gidigidi ní ilẹ̀ náà.

57 Gbogbo ayé ni ó sì ń wá sọ́dọ̀ Josẹfu ní Ijipti tí wọ́n wá ra oúnjẹ, nítorí pé ìyàn náà mú gidigidi ní gbogbo ayé.

Categories
JẸNẸSISI

JẸNẸSISI 42

Àwọn Arakunrin Josẹfu Lọ Ra Ọkà ní Ijipti

1 Nígbà tí Jakọbu gbọ́ pé ọkà wà ní ilẹ̀ Ijipti, ó wí fún àwọn ọmọ rẹ̀ pé, “Kí ni ẹ̀ ń wo ara yín fún?

2 Ẹ wò ó, mo gbọ́ pé ọkà wà ní Ijipti, ẹ lọ ra ọkà wá níbẹ̀ kí ebi má baà pa wá kú.”

3 Àwọn arakunrin Josẹfu mẹ́wàá bá lọ sí Ijipti, wọ́n lọ ra ọkà.

4 Ṣugbọn Jakọbu kò jẹ́ kí Bẹnjamini, arakunrin Josẹfu bá àwọn arakunrin rẹ̀ lọ, nítorí ẹ̀rù ń bà á kí nǹkankan má tún lọ ṣẹlẹ̀ sí òun náà.

5 Àwọn ọmọ Israẹli lọ ra ọkà pẹlu àwọn mìíràn tí wọ́n wá ra ọkà, nítorí kò sí ibi tí ìyàn náà kò dé ní ilẹ̀ Kenaani.

6 Ní gbogbo àkókò yìí, Josẹfu ni gomina ilẹ̀ Ijipti, òun ni ó ń ta ọkà fún àwọn eniyan láti gbogbo orílẹ̀-èdè. Nígbà tí àwọn arakunrin rẹ̀ dé, wọ́n kí i, wọ́n wólẹ̀ níwájú rẹ̀.

7 Josẹfu rí àwọn arakunrin rẹ̀, ó sì mọ̀ wọ́n, ṣugbọn ó bá wọn sọ̀rọ̀ pẹlu ohùn líle bí ẹni pé kò mọ̀ wọ́n rí, ó ní, “Níbo ni ẹ ti wá?”

Wọ́n dá a lóhùn pé, “Láti ilẹ̀ Kenaani ni, oúnjẹ ni a wá rà.”

8 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Josẹfu mọ̀ dájú pé àwọn arakunrin òun ni wọ́n, wọn kò mọ̀ ọ́n.

9 Josẹfu wá ranti àlá rẹ̀ tí ó lá nípa wọn, ó sì wí fún wọn pé, “Amí ni yín, ibi tí àìlera ilẹ̀ yìí wà ni ẹ wá yọ́ wò.”

10 Wọ́n dá a lóhùn pé, “Rárá o, oluwa mi, oúnjẹ ni àwa iranṣẹ rẹ wá rà.

11 Ọmọ baba kan náà ni gbogbo wa, olóòótọ́ eniyan sì ni wá, a kì í ṣe amí.”

12 Josẹfu tún sọ fún wọn pé, “N kò gbà, ibi tí àìlera ilẹ̀ yìí wà ni ẹ wá yọ́ wò.”

13 Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí bẹ̀bẹ̀, wọ́n ní, “Ọkunrin mejila ni àwa iranṣẹ rẹ, tí a jẹ́ ọmọ baba kan náà ní ilẹ̀ Kenaani, èyí tí ó jẹ́ àbíkẹ́yìn wa wà lọ́dọ̀ baba wa nílé, ọ̀kan yòókù ti kú.”

14 Ṣugbọn Josẹfu tẹnumọ́ ọn pé, “Bí mo ti wí gan-an ni ọ̀rọ̀ rí, amí ni yín.

15 Ohun tí n óo fi mọ̀ pé olóòótọ́ ni yín nìyí: mo fi orúkọ Farao búra, ẹ kò ní jáde níhìn-ín àfi bí ẹ bá mú àbíkẹ́yìn baba yín wá.

16 Ẹ rán ọ̀kan ninu yín kí ó lọ mú àbíkẹ́yìn yín wá, ẹ̀yin yòókù ẹ óo wà ninu ẹ̀wọ̀n títí a óo fi mọ̀ bóyá òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ yín, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, mo tún fi orúkọ Farao búra, amí ni yín.”

17 Ó bá da gbogbo wọn sinu ọgbà ẹ̀wọ̀n fún ọjọ́ mẹta.

18 Nígbà tí ó di ọjọ́ kẹta, Josẹfu wí fún wọn pé, “Mo bẹ̀rù Ọlọrun, nítorí náà, bí ẹ bá ṣe ohun tí n óo sọ fun yín yìí, n óo dá ẹ̀mí yín sí.

19 Tí ó bá jẹ́ pé olóòótọ́ eniyan ni yín, kí ọ̀kan ninu yín wà ninu ẹ̀wọ̀n, kí ẹ̀yin yòókù ru ọkà lọ sí ilé fún ìdílé yín tí ebi ń pa,

20 kí ẹ wá mú àbíkẹ́yìn yín tí ẹ̀ ń wí wá, kí n rí i, kí á lè mọ̀ pé òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ yín, ẹ óo sì wà láàyè.”

Wọ́n bá gbà bẹ́ẹ̀.

21 Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí bá ara wọn sọ̀rọ̀ pé, “Dájúdájú, a jẹ̀bi arakunrin wa, nítorí pé a rí ìdààmú ọkàn rẹ̀ nígbà tí ó ń bẹ̀ wá, ṣugbọn a kò dá a lóhùn, ohun tí ó fà á nìyí tí ìdààmú yìí fi dé bá wa.”

22 Reubẹni bá dá wọn lóhùn, ó ní, “Mo sọ fun yín àbí n kò sọ, pé kí ẹ má fi ohunkohun ṣe ọmọ náà? Ṣugbọn ẹ kọ̀, ẹ kò gbọ́, òun nìyí nisinsinyii, ẹ̀san ni ó dé yìí.”

23 Wọn kò mọ̀ pé Josẹfu gbọ́ gbogbo ohun tí wọn ń wí, nítorí pé ògbufọ̀ ni wọ́n fi ń bá ara wọn sọ̀rọ̀.

24 Josẹfu bá kúrò lọ́dọ̀ wọn, ó lọ sọkún, ó tún pada wá láti bá wọn sọ̀rọ̀. Ó mú Simeoni láàrin wọn, ó dè é lókùn.

Àwọn Arakunrin Josẹfu Pada sí Kenaani

25 Josẹfu pàṣẹ pé kí wọ́n di ọkà sinu àpò olukuluku wọn, kí ó kún, kí wọ́n dá owó olukuluku pada sinu àpò rẹ̀, kí wọ́n sì fún wọn ní oúnjẹ tí wọn yóo jẹ lójú ọ̀nà. Wọ́n ṣe fún wọn bí Josẹfu ti wí.

26 Wọ́n di ẹrù wọn ru àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn, wọ́n sì gbọ̀nà ilé.

27 Nígbà tí wọ́n dé ibi tí wọn yóo sùn lálẹ́ ọjọ́ náà, ọ̀kan ninu wọn tú àpò rẹ̀ láti fún kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ ní oúnjẹ, ó bá rí owó rẹ̀ tí wọ́n dì sí ẹnu àpò rẹ̀.

28 Ó wí fún àwọn arakunrin rẹ̀ pé, “Wọ́n dá owó mi pada, òun nìyí lẹ́nu àpò mi yìí.” Nígbà tí wọ́n gbọ́ bẹ́ẹ̀, ẹ̀rù bà wọ́n gidigidi, wọ́n ń wo ara wọn lójú, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí gbọ̀n, wọ́n ní, “Irú kí ni Ọlọrun ṣe sí wa yìí?”

29 Nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ Jakọbu baba wọn ní ilẹ̀ Kenaani, wọ́n kó gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí wọn, wọ́n rò fún un, wọ́n ní,

30 “Ọkunrin tíí ṣe alákòóso ilẹ̀ náà sọ̀rọ̀ líle sí wa, ó ṣebí a wá ṣe amí ilẹ̀ náà ni.

31 Ṣugbọn a wí fún un pé, ‘Olóòótọ́ ni wá, a kì í ṣe eniyankeniyan, ati pé a kì í ṣe amí rárá.

32 Ọkunrin mejila ni àwa tí a jẹ́ ọmọ baba kan náà, ọ̀kan ninu wa ti kú, èyí tí ó kéré jù sì wà lọ́dọ̀ baba wa ní ilẹ̀ Kenaani.’

33 Ọkunrin náà bá dáhùn pé, ohun tí yóo jẹ́ kí òun mọ̀ pé olóòótọ́ eniyan ni wá ni pé kí á fi ọ̀kan ninu wa sílẹ̀ lọ́dọ̀ òun, kí á gbé ọkà lọ sílé, kí ebi má baà pa ìdílé wa.

34 Kí á mú àbúrò wa patapata wá fún òun, nígbà náà ni òun yóo tó mọ̀ pé a kì í ṣe amí, ati pé olóòótọ́ eniyan ni wá, òun óo sì dá arakunrin wa pada fún wa, a óo sì ní anfaani láti máa ṣòwò ní ilẹ̀ Kenaani.”

35 Bí wọ́n ti tú àpò wọn, olukuluku bá owó rẹ̀ lẹ́nu àpò rẹ̀. Nígbà tí àwọn ati baba wọn rí èyí, àyà wọn já.

36 Jakọbu baba wọn bá sọ fún wọn, ó ní, “Ẹ ti jẹ́ kí n ṣòfò àwọn ọmọ mi: Josẹfu ti kú, Simeoni kò sí mọ́, ẹ tún fẹ́ mú Bẹnjamini lọ. Èmi nìkan ni gbogbo èyí ṣẹlẹ̀ sí tán!”

37 Reubẹni bá wí fún baba rẹ̀ pé, “Pa àwọn ọmọ mi mejeeji, bí n kò bá mú Bẹnjamini pada wá fún ọ. Fi lé mi lọ́wọ́, n óo sì mú un pada wá fún ọ.”

38 Ṣugbọn Jakọbu dáhùn, ó ní, “Ọmọ tèmi kò ní bá yín lọ, nítorí pé ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ti kú, òun nìkan ni ó kù. Bí ohunkohun bá ṣẹlẹ̀ sí i ní ìrìn àjò tí ẹ fẹ́ lọ yìí, mo ti darúgbó, ìbànújẹ́ rẹ̀ ni yóo rán mi sọ́run.”

Categories
JẸNẸSISI

JẸNẸSISI 43

Àwọn Arakunrin Josẹfu Pada Lọ sí Ijipti pẹlu Bẹnjamini

1 Ìyàn tí ó mú ní ilẹ̀ Kenaani ṣá túbọ̀ ń pọ̀ sí i ni.

2 Nígbà tí wọ́n jẹ ọkà tí wọ́n rà ní Ijipti tán, baba wọn pè wọ́n, ó ní, “Ẹ tún wá lọ ra oúnjẹ díẹ̀ sí i.”

3 Ṣugbọn Juda dá a lóhùn, ó ní, “Ọkunrin náà kìlọ̀ fún wa gidigidi pé a kò ní fi ojú kan òun láìjẹ́ pé a mú arakunrin wa lọ́wọ́.

4 Bí o bá jẹ́ kí arakunrin wa bá wa lọ, a óo lọ ra oúnjẹ wá fún ọ,

5 ṣugbọn bí o kò bá jẹ́ kí ó bá wa lọ, a kò ní lọ, nítorí pé ọkunrin náà tẹnumọ́ ọn fún wa pé a kò ní fi ojú kan òun láìjẹ́ pé arakunrin wa bá wa wá.”

6 Israẹli ní, “Irú ọ̀ràn ńlá wo ni ẹ tún dá sí mi lọ́rùn yìí, tí ẹ lọ sọ fún ọkunrin náà pé ẹ ní arakunrin mìíràn?”

7 Wọ́n dá a lóhùn pé, “Kò sí ohun tí ọkunrin náà kò bi wá tán nípa ará ati ẹbí wa, ó ní, ‘Ǹjẹ́ baba yín wà láàyè? Ǹjẹ́ ẹ tún ní arakunrin mìíràn?’ Àwọn ìbéèrè tí ó ń bèèrè ni ó mú kí á sọ ohun tí a sọ fún un. Báwo ni a ṣe lè mọ̀ pé yóo sọ pé kí á mú àbúrò wa wá?”

8 Juda bá sọ fún Israẹli, ó ní, “Fa ọmọ náà lé mi lọ́wọ́, a óo sì lọ kí á lè wà láàyè, kí ebi má baà pa ẹnikẹ́ni kú ninu wa, ati àwọn ọmọ wa kéékèèké.

9 N óo dúró fún ọmọ náà, ọwọ́ mi ni kí o ti bèèrè rẹ̀. Bí n kò bá mú un pada, kí n sì fà á lé ọ lọ́wọ́, da ẹ̀bi rẹ̀ lé mi lórí títí lae,

10 nítorí pé bí a kò bá fi ìrìn àjò yìí falẹ̀ ni, à bá ti lọ, à bá sì ti dé, bí ẹẹmeji.”

11 Israẹli, baba wọn bá sọ fún wọn pé, “Bí ó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, ó dára, báyìí ni kí ẹ ṣe, ẹ dì ninu àwọn èso tí ó dára jùlọ ní ilẹ̀ yìí sinu àpò yín, kí ẹ gbé e lọ fún ọkunrin náà. Ẹ mú ìpara díẹ̀, oyin díẹ̀, turari díẹ̀ ati òjíá díẹ̀, ẹ mú èso pistakio ati èso alimọndi pẹlu.

12 Ìlọ́po meji owó ọjà tí ẹ óo rà ni kí ẹ mú lọ́wọ́, ẹ mú owó tí ó wà lẹ́nu àpò yín níjelòó lọ́wọ́ pẹlu, bóyá wọ́n gbàgbé ni.

13 Ẹ mú arakunrin yín náà lọ́wọ́, kí ẹ sì tọ ọkunrin náà lọ.

14 Kí Ọlọrun Olodumare jẹ́ kí ọkunrin náà ṣàánú yín, kí ó sì dá arakunrin yín kan yòókù ati Bẹnjamini pada. Bí mo bá tilẹ̀ wá ṣòfò àwọn ọmọ mi nígbà náà, n óo gbà pé mo ṣòfò wọn.”

15 Àwọn ọkunrin náà bá gbé ẹ̀bùn náà, wọ́n sì mú ìlọ́po meji owó tí wọ́n nílò, ati Bẹnjamini, wọ́n lọ siwaju Josẹfu ní Ijipti.

16 Nígbà tí Josẹfu rí Bẹnjamini pẹlu wọn, ó sọ fún alabojuto ilé rẹ̀, ó ní, “Mú àwọn ọkunrin wọnyi wọlé, pa ẹran kan kí o sì sè é, nítorí wọn yóo bá mi jẹun lọ́sàn-án yìí.”

17 Ọkunrin náà ṣe bí Josẹfu ti pàṣẹ fún un, ó sì mú àwọn ọkunrin náà wọ ilé Josẹfu lọ.

18 Ẹ̀rù bẹ̀rẹ̀ sí bà wọ́n nígbà tí Josẹfu mú wọn wọ ilé rẹ̀, wọ́n ń wí fún ara wọn pé, “Nítorí owó tí wọ́n fi sí ẹnu àpò wa níjelòó ni wọ́n fi kó wa wọlé, kí ó lè rí ẹ̀sùn kà sí wa lẹ́sẹ̀, kí ó lè fi wá ṣe ẹrú, kí ó sì kó àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wa.”

19 Wọ́n bá tọ alabojuto ilé Josẹfu lọ lẹ́nu ọ̀nà,

20 wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bẹ̀bẹ̀, wọ́n ní, “Jọ̀wọ́ oluwa mi, a ti kọ́kọ́ wá ra oúnjẹ níhìn-ín nígbà kan.

21 Nígbà tí à ń pada lọ tí a dé ibi tí a fẹ́ sùn, a tú àpò wa, olukuluku wa bá owó tirẹ̀ lẹ́nu àpò rẹ̀, kò sí ti ẹni tí ó dín rárá, a mú owó náà lọ́wọ́ báyìí.

22 A sì tún mú owó mìíràn lọ́wọ́ pẹlu láti ra oúnjẹ. A kò mọ ẹni tí ó dá owó wa pada sinu àpò wa.”

23 Ó dá wọn lóhùn, ó ní, “Ẹ fọkàn yín balẹ̀, ẹ má bẹ̀rù, ó níláti jẹ́ pé Ọlọrun yín ati ti baba yín ni ó fi owó náà sinu àpò yín fun yín, mo gba owó lọ́wọ́ yín.” Ó bá mú Simeoni jáde sí wọn.

24 Ọkunrin náà mú wọn wọ inú ilé Josẹfu, ó fún wọn ní omi, wọ́n fọ ẹsẹ̀ wọn, wọ́n sì fún àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn ní oúnjẹ.

25 Lẹ́yìn náà wọ́n tọ́jú ẹ̀bùn Josẹfu sílẹ̀ di ìgbà tí yóo dé lọ́sàn-án, nítorí wọ́n gbọ́ pé ibẹ̀ ni wọn yóo ti jẹun.

26 Nígbà tí Josẹfu wọlé, wọ́n mú ẹ̀bùn tí wọ́n mú bọ̀ fún un wọlé tọ̀ ọ́ lọ, wọ́n sì wólẹ̀ fún un, wọ́n dojúbolẹ̀.

27 Ó bèèrè alaafia wọn, ó ní, “Ṣé alaafia ni baba yín wà, arúgbó tí ẹ sọ̀rọ̀ rẹ̀ fún mi? Ṣé ó ṣì wà láàyè?”

28 Wọ́n dá a lóhùn, wọ́n ní, “Baba wa, iranṣẹ rẹ ń bẹ láàyè, ó sì wà ní alaafia.” Wọ́n tẹríba, wọ́n bu ọlá fún un.

29 Ojú tí ó gbé sókè, ó rí Bẹnjamini ọmọ ìyá rẹ̀, ó bá bèèrè pé, “Ṣé arakunrin yín tí í ṣe àbíkẹ́yìn tí ẹ wí nìyí? Kí Ọlọrun fi ojurere wò ọ́, ọmọ mi.”

30 Josẹfu bá yára jáde kúrò lọ́dọ̀ wọn nítorí pé ọkàn rẹ̀ fà sí àbúrò rẹ̀, orí rẹ̀ sì wú, ó wá ibìkan láti lọ sọkún. Ó bá wọ yàrá rẹ̀, ó lọ sọkún níbẹ̀.

31 Lẹ́yìn náà ó bọ́ ojú rẹ̀, ó jáde, ó gbìyànjú, ó dárayá, ó ní, “Ẹ gbé oúnjẹ wá.”

32 Wọ́n gbé oúnjẹ tirẹ̀ kalẹ̀ lọ́tọ̀, ti àwọn arakunrin rẹ̀ lọ́tọ̀, ati ti àwọn ará Ijipti tí wọn ń bá a jẹun lọ́tọ̀, nítorí pé ìríra ni ó jẹ́ fún àwọn ará Ijipti láti bá àwọn Heberu jẹun pọ̀.

33 Àwọn arakunrin Josẹfu jókòó níwájú rẹ̀, wọ́n tò wọ́n gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ orí wọn, láti orí ẹ̀gbọ́n patapata dé orí àbúrò patapata. Nígbà tí àwọn arakunrin Josẹfu rí i bí wọ́n ti tò wọ́n, wọ́n ń wo ara wọn lójú tìyanu-tìyanu.

34 Láti orí tabili Josẹfu ni wọ́n ti bu oúnjẹ fún olukuluku, ṣugbọn oúnjẹ ti Bẹnjamini tó ìlọ́po marun-un ti ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn. Wọ́n bá a jẹ, wọ́n mu, wọ́n sì bá a ṣe àríyá.

Categories
JẸNẸSISI

JẸNẸSISI 44

Ife Tí Ó Sọnù

1 Josẹfu pàṣẹ fún alabojuto ilé rẹ̀, ó ní, “Ẹ di ọkà kún àpò àwọn ọkunrin wọnyi, bí wọ́n bá ti lè rù tó, kí ẹ sì fi owó olukuluku wọn sí ẹnu àpò rẹ̀,

2 kí ẹ wá fi ife fadaka mi sí ẹnu àpò èyí àbíkẹ́yìn wọn, pẹlu owó tí ó fi ra ọkà.” Ọkunrin náà sì ṣe gẹ́gẹ́ bí Josẹfu ti pàṣẹ fún un.

3 Bí ilẹ̀ ọjọ́ keji ti mọ́, wọ́n ní kí àwọn arakunrin Josẹfu máa lọ ati àwọn ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn.

4 Nígbà tí wọn kò tíì rìn jìnnà sí ìlú, Josẹfu sọ fún alabojuto ilé rẹ̀ pé, “Gbéra, sáré tẹ̀lé àwọn ọkunrin náà, nígbà tí o bá bá wọn, wí fún wọn pé, ‘Èéṣe tí ẹ fi fi ibi sú olóore? Èéṣe tí ẹ fi jí ife fadaka ọ̀gá mi?

5 Ife yìí ni ọ̀gá mi fi ń mu omi, ife yìí kan náà ni ó sì fi ń woṣẹ́, ọ̀ràn ńlá gan-an ni ẹ dá yìí.’ ”

6 Nígbà tí ó lé wọn bá, ó wí fún wọn bí Josẹfu ti kọ́ ọ.

7 Wọ́n dá a lóhùn, wọ́n ní, “Èéṣe tí o fi ń sọ̀rọ̀ sí wa báyìí? Kí á má rí i, pé àwa iranṣẹ rẹ ṣe ohun tí ó jọ bẹ́ẹ̀.

8 Ṣé o ranti pé owó tí a bá lẹ́nu àpò wa, a mú un pada ti ilẹ̀ Kenaani wá fún ọ? Kí ni ìbá dé tí a óo fi jí fadaka tabi wúrà ní ilé ọ̀gá rẹ?

9 Bí wọ́n bá bá a lọ́wọ́ èyíkéyìí ninu àwa iranṣẹ rẹ, pípa ni kí wọ́n pa olúwarẹ̀, kí àwa yòókù sì di ẹrú rẹ.”

10 Ó dá wọn lóhùn, ó ní, “Bí ẹ ti wí gan-an ni yóo rí. Ọwọ́ ẹni tí a bá ti bá a ni yóo di ẹrú mi, kò sí ohun tí ó kan ẹ̀yin yòókù rárá.”

11 Gbogbo wọn bá sọ àpò wọn kalẹ̀, wọ́n tú wọn.

12 Iranṣẹ náà bá bẹ̀rẹ̀ sí wo àpò wọn, ó bẹ̀rẹ̀ lórí àpò èyí àgbà patapata, títí dé orí ti àbíkẹ́yìn wọn, wọ́n bá ife náà ninu ẹrù Bẹnjamini.

13 Wọ́n fa aṣọ wọn ya láti fi ìbànújẹ́ wọn hàn, olukuluku wọn bá di ẹrù rẹ̀ ru kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, wọ́n pada lọ sí ààrin ìlú.

14 Nígbà tí Juda ati àwọn arakunrin rẹ̀ pada dé ilé Josẹfu, ó ṣì wà nílé, wọ́n bá dọ̀bálẹ̀ gbalaja níwájú rẹ̀.

15 Josẹfu bi wọ́n léèrè, ó ní, “Irú kí ni ẹ dánwò yìí? Ó jọ bí ẹni pé ẹ kò lérò pé irú mi lè woṣẹ́ ni?”

16 Juda dá a lóhùn, ó ní, “Kí ni a rí tí a lè wí fún ọ, oluwa mi? Ọ̀rọ̀ wo ni ó lè dùn lẹ́nu wa? Ọṣẹ wo ni a lè fi wẹ̀, tí a fi lè mọ́? Ọlọrun ti rí ẹ̀bi àwa iranṣẹ rẹ. Wò ó, a di ẹrú rẹ, oluwa mi, ati àwa ati ẹni tí wọ́n bá ife náà lọ́wọ́ rẹ̀.”

17 Ṣugbọn ó dá wọn lóhùn, ó ní, “Kí á má rí i pé mo ṣe ohun tí ó jọ bẹ́ẹ̀. Ẹnìkan ṣoṣo tí wọ́n ká ife náà mọ́ lọ́wọ́ ni yóo di ẹrú mi, ní tiyín, ẹ máa pada tọ baba yín lọ ní alaafia.”

Juda Bẹ̀bẹ̀ fún Ìdásílẹ̀ Bẹnjamini

18 Juda bá tọ̀ ọ́ lọ, ó ní, “Jọ̀wọ́, oluwa mi, jẹ́ kí n sọ gbolohun ọ̀rọ̀ kan, má jẹ́ kí inú bí ọ sí èmi, iranṣẹ rẹ, nítorí kò sí ìyàtọ̀, bíi Farao ni o rí.

19 Oluwa mi, ranti pé o bi àwa iranṣẹ rẹ pé, ‘Ǹjẹ́ ẹ ní baba tabi arakunrin mìíràn?’

20 A sì dá oluwa mi lóhùn pé, ‘A ní baba, ó ti di arúgbó, a sì ní arakunrin kan pẹlu, tí baba yìí fi arúgbó ara bí, ati pé ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ti kú, òun nìkan ṣoṣo ni ó kù lọ́mọ ìyá tirẹ̀, baba rẹ̀ sì fẹ́ràn rẹ̀.’

21 O sọ fún àwa iranṣẹ rẹ pé kí á mú un tọ̀ ọ́ wá, kí o lè fi ojú rí i.

22 A sì sọ fún ọ pé, ‘Ọmọ náà kò lè fi baba rẹ̀ sílẹ̀, nítorí pé bí ó bá fi baba rẹ̀ sílẹ̀, baba rẹ̀ yóo kú.’

23 O bá sọ fún àwa iranṣẹ rẹ pé bí àbíkẹ́yìn wa patapata kò bá bá wa wá, a kò ní rí ojú rẹ nílẹ̀ mọ́.

24 “Nígbà tí a pada dé ọ̀dọ̀ baba wa, iranṣẹ rẹ, a rò fún un bí o ti wí.

25 Nígbà tí ó ní kí á tún lọ ra oúnjẹ díẹ̀ wá,

26 a wí fún un pé, a kò ní lọ, àfi bí arakunrin wa bá tẹ̀lé wa, nítorí pé a kò ní rí ojú rẹ nílẹ̀ bí kò bá bá wa wá.

27 Baba wa sọ fún wa pé a mọ̀ pé ọkunrin meji ni Rakẹli, aya òun bí fún òun,

28 ọ̀kan fi òun sílẹ̀, òun sì wí pé, dájúdájú, ẹranko kan ti fà á ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, òun kò sì tíì fi ojú òun kàn án láti ìgbà náà.

29 Ó ní bí a bá tún mú eléyìí kúrò lọ́dọ̀ òun, bí ohun burúkú kan bá ṣẹlẹ̀ sí i, pẹlu arúgbó ara òun yìí, ìbànújẹ́ rẹ̀ ni yóo pa òun.

30 “Nítorí náà, bí mo bá pada dé ọ̀dọ̀ baba mi tí n kò sì mú ọmọdekunrin náà lọ́wọ́, níwọ̀n ìgbà tí ó jẹ́ pé ọmọdekunrin yìí gan-an ni ó fi ẹ̀mí tẹ̀,

31 bí kò bá rí i pẹlu wa, kíkú ni yóo kú. Yóo sì wá jẹ́ pé àwa ni a fa ìbànújẹ́ fún baba wa, ní ọjọ́ ogbó rẹ̀, ìbànújẹ́ yìí ni yóo sì pa á.

32 Èmi ni mo dúró fún ọmọdekunrin náà lọ́dọ̀ baba wa, mo wí fún un pé, ‘Bí n kò bá mú ọmọ yìí pada, ẹ̀bi rẹ̀ yóo wà lórí mi ní gbogbo ọjọ́ ayé mi.’

33 Nígbà tí ọ̀rọ̀ wá rí bí ó ti rí yìí, oluwa mi, jọ̀wọ́, jẹ́ kí èmi di ẹrú rẹ dípò ọmọdekunrin yìí, jẹ́ kí òun máa bá àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ pada lọ.

34 Báwo ni n óo ṣe pada dé iwájú baba mi láìmú ọmọ náà lọ́wọ́? Ẹ̀rù ohun burúkú tí yóo ṣẹlẹ̀ sí baba mi, ń bà mí.”

Categories
JẸNẸSISI

JẸNẸSISI 45

Josẹfu Farahan Àwọn Arakunrin Rẹ̀

1 Josẹfu kò lè mú ọ̀rọ̀ yìí mọ́ra mọ́ lójú gbogbo àwọn tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀, ó bá kígbe, ó ní, “Gbogbo yín patapata, ẹ jáde kúrò lọ́dọ̀ mi.” Nítorí náà, kò sí ẹnikẹ́ni lọ́dọ̀ Josẹfu nígbà tí ó fi ara rẹ̀ han àwọn arakunrin rẹ̀ pé òun ni Josẹfu.

2 Ó bú sẹ́kún, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí pohùnréré ẹkún tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn ará Ijipti ati gbogbo ilé Farao gbọ́ ẹkún rẹ̀.

3 Josẹfu sọ fún àwọn arakunrin rẹ̀ pé òun ni Josẹfu. Ó bi wọ́n léèrè pé ǹjẹ́ baba òun ṣì wà láàyè. Ṣugbọn jìnnìjìnnì dà bo àwọn arakunrin rẹ̀ níwájú rẹ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí wọn kò lè dáhùn.

4 Josẹfu bá bẹ̀rẹ̀ sí rọ̀ wọ́n, ó ní kí wọ́n jọ̀wọ́, kí wọ́n súnmọ́ òun. Ó tún wí fún wọn pé òun ni Josẹfu arakunrin wọn, tí wọ́n tà sí Ijipti.

5 Ó ní, “Ẹ má wulẹ̀ dààmú ẹ̀mí ara yín, ẹ má sì bínú sí ara yín pé ẹ tà mí síhìn-ín. Ọlọrun fúnrarẹ̀ ni ó rán mi ṣáájú yín láti gba ẹ̀mí là.

6 Nítorí ó ti di ọdún keji tí ìyàn yìí ti bẹ̀rẹ̀ ní ilẹ̀ yìí, ó sì ku ọdún marun-un gbáko tí kò fi ní sí ìfúrúgbìn tabi ìkórè.

7 Ọlọrun ni ó rán mi ṣáájú yín láti dá yín sí, ati láti gba ọpọlọpọ ẹ̀mí là ninu ìran yín.

8 Nítorí náà, kì í ṣe ẹ̀yin ni ẹ gbé mi dé ìhín, Ọlọrun ni, ó sì ti fi mí ṣe baba fún Farao, ati oluwa ninu gbogbo ilé rẹ̀ ati alákòóso gbogbo ilẹ̀ Ijipti.

9 “Ẹ ṣe kíá, ẹ wá lọ sọ́dọ̀ baba mi kí ẹ wí fún un pé, Josẹfu ọmọ rẹ̀ wí pé, Ọlọrun ti fi òun ṣe olórí ní gbogbo ilẹ̀ Ijipti, ẹ ní mo ní kí ó máa bọ̀ lọ́dọ̀ mi kíákíá.

10 Ẹ sọ fún un pé mo sọ pé kí ó wá máa gbé ní ilẹ̀ Goṣeni nítòsí mi, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀, ati àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀, ati agbo mààlúù rẹ̀, ati ohun gbogbo tí ó ní.

11 N óo máa tọ́jú rẹ̀ níbẹ̀, nítorí pé ó tún ku ọdún marun-un gbáko kí ìyàn yìí tó kásẹ̀ nílẹ̀, kí òun ati ìdílé rẹ̀ ati gbogbo àwọn eniyan rẹ̀ má baà di aláìní.

12 “Ẹ̀yin pàápàá fi ojú rí i, Bẹnjamini arakunrin mi náà sì rí i pẹlu pé èmi gan-an ni mò ń ba yín sọ̀rọ̀.

13 Ẹ níláti sọ fún baba mi nípa gbogbo ògo mi ní Ijipti, ati gbogbo ohun tí ẹ ti rí. Ẹ tètè yára mú baba mi wá bá mi níhìn-ín.”

14 Ó bá rọ̀ mọ́ Bẹnjamini arakunrin rẹ̀ lọ́rùn, ó sì bú sẹ́kún, bí Bẹnjamini náà ti rọ̀ mọ́ ọn, ni òun náà bú sẹ́kún.

15 Josẹfu bá fi ẹnu ko àwọn arakunrin rẹ̀ lẹ́nu lọ́kọ̀ọ̀kan, ó sì sọkún, lẹ́yìn náà ni àwọn arakunrin rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí bá a sọ̀rọ̀.

16 Nígbà tí gbogbo ìdílé Farao gbọ́ pé àwọn arakunrin Josẹfu dé, inú Farao ati àwọn iranṣẹ rẹ̀ dùn pupọ.

17 Farao sọ fún Josẹfu pé kí ó sọ fún àwọn arakunrin rẹ̀ kí wọ́n múra, kí wọ́n di ẹrù ru àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn, kí wọ́n tètè pada lọ sí Kenaani,

18 kí wọ́n sì lọ mú baba rẹ̀ ati gbogbo àwọn ará ilé rẹ̀ wá sọ́dọ̀ òun. Ó ní òun óo fún un ní ibi tí ó dára jùlọ ní ilẹ̀ Ijipti, wọn yóo sì jẹ àjẹyó ninu ilẹ̀ náà.

19 Ó ní kí Josẹfu pàṣẹ fún wọn pẹlu kí wọ́n kó kẹ̀kẹ́ ẹlẹ́ṣin láti ilẹ̀ Ijipti, láti fi kó àwọn ọmọde ati àwọn obinrin, kí baba wọn náà sì máa bá wọn bọ̀.

20 Ó ní kí wọ́n má ronú àwọn dúkìá wọn nítorí àwọn ni wọn yóo ni ilẹ̀ tí ó dára jù ní Ijipti.

21 Àwọn ọmọ Israẹli ṣe bí ọba ti wí, Josẹfu fún wọn ní kẹ̀kẹ́ ẹlẹ́ṣin gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Farao, ó sì fún wọn ní oúnjẹ tí wọn yóo máa jẹ lọ́nà.

22 Ó fún olukuluku wọn ní ìpààrọ̀ aṣọ kọ̀ọ̀kan, ṣugbọn ó fún Bẹnjamini ní ọọdunrun (300) ṣekeli fadaka ati ìpààrọ̀ aṣọ marun-un.

23 Ó di àwọn nǹkan dáradára ilẹ̀ Ijipti ru kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ mẹ́wàá, ó di ọkà ati oúnjẹ ru abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ mẹ́wàá, ó kó wọn ranṣẹ sí baba rẹ̀ pé kí ó rí ohun máa jẹ bọ̀ lọ́nà.

24 Ó bá ní kí àwọn arakunrin òun máa lọ, bí wọ́n sì ti fẹ́ máa lọ, ó kìlọ̀ fún wọn pé kí wọ́n má bá ara wọn jà lọ́nà.

25 Wọ́n bá kúrò ní Ijipti, wọ́n pada sọ́dọ̀ Jakọbu baba wọn ní ilẹ̀ Kenaani.

26 Wọ́n sọ fún un pé, “Josẹfu kò kú, ó wà láàyè, ati pé òun ni alákòóso gbogbo ilẹ̀ Ijipti.” Nígbà tí ó gbọ́ bẹ́ẹ̀, orí rẹ̀ fò lọ fee, kò kọ́ gbà wọ́n gbọ́.

27 Ṣugbọn nígbà tí ó gbọ́ gbogbo ohun tí Josẹfu wí fún wọn, tí ó tún rí kẹ̀kẹ́ ẹlẹ́ṣin tí Josẹfu fi ranṣẹ pé kí wọ́n fi gbé òun wá, ara rẹ̀ wálẹ̀.

28 Israẹli bá dáhùn, ó ní, “Josẹfu, ọmọ mi wà láàyè! Ó ti parí, n óo lọ fi ojú kàn án kí n tó kú.”

Categories
JẸNẸSISI

JẸNẸSISI 46

Jakọbu ati Ìdílé Rẹ̀ Lọ sí Ijipti

1 Israẹli di gbogbo ohun tí ó ní, ó kó lọ sí Beeriṣeba, ó lọ rúbọ sí Ọlọrun Isaaki, baba rẹ̀.

2 Ọlọrun bá a sọ̀rọ̀ lójú ìran lóru, ó pè é, ó ní, “Jakọbu, Jakọbu.”

Ó dáhùn, ó ní, “Èmi nìyí.”

3 Ọlọrun wí pé, “Èmi ni Ọlọrun baba rẹ, má fòyà rárá láti lọ sí Ijipti, nítorí pé n óo sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè ńlá níbẹ̀.

4 N óo bá ọ lọ sí Ijipti, n óo sì tún mú ọ pada wá, ọwọ́ Josẹfu ni o óo sì dákẹ́ sí.”

5 Jakọbu bá bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò rẹ̀ láti Beeriṣeba. Àwọn ọmọ rẹ̀ gbé e sinu ọkọ̀ tí Farao fi ranṣẹ sí i pé kí wọ́n fi gbé e wá, wọ́n sì kó àwọn iyawo wọn ati àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ pẹlu wọn.

6 Wọ́n kó àwọn ẹran ọ̀sìn wọn ati gbogbo ohun tí wọ́n ní ní ilẹ̀ Kenaani, wọ́n lọ sí Ijipti.

7 Gbogbo ilé rẹ̀ patapata ni Jakọbu kó lọ́wọ́ lọ sí Ijipti, ati àwọn ọmọ rẹ̀, ati àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀, lọkunrin ati lobinrin, gbogbo wọn ni ó kó lọ sí Ijipti patapata.

8 Ìwọ̀nyí ni orúkọ àwọn ọmọ ati àwọn ọmọ ọmọ Israẹli tí wọ́n lọ sí ilẹ̀ Ijipti, Jakọbu ati àwọn ọmọ rẹ̀: Reubẹni, àkọ́bí rẹ̀,

9 ati àwọn ọmọ Reubẹni wọnyi: Hanoku, Palu, Hesironi, ati Karimi.

10 Àwọn ọmọ ti Simeoni ni: Jemueli, Jamini, Ohadi, Jakini, Sohari, ati Ṣaulu, tí obinrin ará Kenaani bí fún un.

11 Àwọn ọmọ ti Lefi ni: Geriṣoni, Kohati, ati Merari.

12 Àwọn ọmọ ti Juda ni: Eri, Onani, Ṣela, Peresi, ati Sera, (ṣugbọn, Eri ati Onani ti kú ní ilẹ̀ Kenaani) àwọn ọmọ ti Peresi ni Hesironi ati Hamuli.

13 Àwọn ọmọ ti Isakari ni: Tola, Pua, Jobu ati Ṣimironi.

14 Àwọn ọmọ ti Sebuluni ni: Seredi, Eloni, ati Jaleeli.

15 (Àwọn ni ọmọ tí Lea bí fún Jakọbu ní Padani-aramu ati Dina, ọmọ rẹ̀ obinrin.) Gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ lọkunrin ati lobinrin jẹ́ mẹtalelọgbọn.

16 Àwọn ọmọ ti Gadi ni: Sifioni, Hagi, Ṣuni, Esiboni, Eri, Arodu, ati Areli.

17 Àwọn ọmọ ti Aṣeri ni: Imina, Iṣifa, Iṣifi, Beraya, ati Sera arabinrin wọn. Àwọn ọmọ ti Beraya ni Heberi, ati Malikieli.

18 (Àwọn ni ọmọ tí Silipa bí fún Jakọbu. Silipa ni iranṣẹ tí Labani fún Lea ọmọ rẹ̀ obinrin, gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ jẹ́ mẹrindinlogun.)

19 Àwọn ọmọ ti Rakẹli ni Josẹfu ati Bẹnjamini.

20 Asenati, ọmọbinrin Pọtifera bí Manase ati Efuraimu fún Josẹfu ní ilẹ̀ Ijipti. Pọtifera ni babalóòṣà oriṣa Oni, ní Ijipti.

21 Àwọn ọmọ ti Bẹnjamini ni: Bela, Bekeri, Aṣibeli, Gera, Naamani, Ehi, Roṣi, Mupimu, Hupimu, ati Aridi,

22 (àwọn wọnyi ni ọmọ tí Rakẹli bí fún Jakọbu ati àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀. Gbogbo wọn jẹ́ mẹrinla).

23 Ọmọ ti Dani ni Huṣimu.

24 Àwọn ọmọ ti Nafutali ni Jaseeli, Guni, Jeseri, ati Ṣilemu.

25 (Àwọn ọmọ tí Biliha bí fún Jakọbu ati àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀ jẹ́ meje), Biliha ni iranṣẹbinrin tí Labani fún Rakẹli, ọmọ rẹ̀ obinrin.

26 Gbogbo àwọn tí wọ́n bá Jakọbu lọ sí Ijipti, tí wọ́n jẹ́ ọmọ tabi ọmọ ọmọ rẹ̀ jẹ́ mẹrindinlaadọrin, láìka àwọn iyawo àwọn ọmọ rẹ̀.

27 Àwọn ọmọ tí Josẹfu bí ní Ijipti jẹ́ meji. Gbogbo eniyan tí ó ti ìdílé Jakọbu jáde lọ sí Ijipti patapata wá jẹ́ aadọrin.

Jakọbu ati Ìdílé Rẹ̀ ní Ijipti

28 Jakọbu rán Juda ṣáájú lọ sọ́dọ̀ Josẹfu pé kí Josẹfu wá pàdé òun ní Goṣeni, wọ́n sì wá sí ilẹ̀ Goṣeni.

29 Josẹfu bọ́ sinu kẹ̀kẹ́ ẹlẹ́ṣin rẹ̀, ó lọ pàdé Israẹli, baba rẹ̀ ní Goṣeni. Nígbà tí Josẹfu dé ọ̀dọ̀ baba rẹ̀, ó rọ̀ mọ́ ọn lọ́rùn, ó sì sọkún fún ìgbà pípẹ́.

30 Israẹli bá wí fún Josẹfu, ó ní, “Níwọ̀n ìgbà tí mo ti fi ojú kàn ọ́ báyìí, tí mo sì rí i pé o wà láàyè, bí ikú bá tilẹ̀ wá dé, ó yá mi.”

31 Josẹfu sọ fún àwọn arakunrin rẹ̀ ati gbogbo ìdílé baba rẹ̀ pé òun óo lọ sọ fún Farao pé àwọn arakunrin òun ati ìdílé baba òun tí wọ́n wà ní ilẹ̀ Kenaani ti dé sọ́dọ̀ òun.

32 Ati pé darandaran ni wọ́n, ìtọ́jú ẹran ọ̀sìn ni iṣẹ́ wọn, wọ́n sì kó gbogbo agbo mààlúù ati agbo ewúrẹ́, ati ohun gbogbo tí wọ́n ní lọ́wọ́ wá.

33 Ó ní nígbà tí Farao bá pè wọ́n, tí ó bá bi wọ́n léèrè pé irú iṣẹ́ wo ni wọ́n ń ṣe,

34 kí wọ́n dá a lóhùn pé, ẹran ọ̀sìn ni àwọn ti ń tọ́jú láti ìgbà èwe àwọn títí di ìsinsìnyìí, ati àwọn ati àwọn baba àwọn, kí ó lè jẹ́ kí wọ́n máa gbé ilẹ̀ Goṣeni, nítorí pé ìríra patapata ni gbogbo darandaran jẹ́ fún àwọn ará Ijipti.

Categories
JẸNẸSISI

JẸNẸSISI 47

1 Josẹfu bá wọlé lọ sọ fún Farao pé, “Baba mi ati àwọn arakunrin mi ti dé láti ilẹ̀ Kenaani, pẹlu gbogbo agbo ẹran ati agbo mààlúù wọn, ati ohun gbogbo tí wọ́n ní, wọ́n sì wà ní ilẹ̀ Goṣeni báyìí.”

2 Ó mú marun-un ninu àwọn arakunrin rẹ̀, ó fi wọ́n han Farao.

3 Farao bi àwọn arakunrin rẹ̀ léèrè irú iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe.

Wọ́n dá Farao lóhùn pé, darandaran ni àwọn gẹ́gẹ́ bí àwọn baba wọn.

4 Wọ́n tún wí fún Farao pé, àwọn wá láti ṣe àtìpó ní ilẹ̀ rẹ̀ ni, nítorí pé ìyàn ńlá tí ó mú ní ilẹ̀ Kenaani kò jẹ́ kí koríko wà fún àwọn ẹran àwọn. Wọ́n ní àwọn wá bẹ Farao ni, pé kí ó jẹ́ kí àwọn máa gbé ilẹ̀ Goṣeni.

5 Farao bá sọ fún Josẹfu pé, “Ọ̀dọ̀ rẹ ni baba rẹ ati àwọn arakunrin rẹ wá.

6 Wo ilẹ̀ Ijipti láti òkè dé ilẹ̀, ibikíbi tí o bá rí i pé ó dára jùlọ ninu gbogbo ilẹ̀ náà ni kí o fi baba rẹ ati àwọn arakunrin rẹ sí. Jẹ́ kí wọ́n máa gbé ilẹ̀ Goṣeni, bí o bá sì mọ èyíkéyìí ninu wọn tí ó lè bojútó àwọn ẹran ọ̀sìn dáradára, fi ṣe alabojuto àwọn ẹran ọ̀sìn mi.”

7 Josẹfu bá mú Jakọbu baba rẹ̀ wọlé láti fihan Farao, Jakọbu sì súre fún Farao.

8 Farao bi Jakọbu pé, “Ẹni ọdún mélòó ni ọ́ báyìí?”

9 Jakọbu dá a lóhùn pé, “Ọjọ́ orí mi jẹ́ aadoje (130) ọdún. Ọjọ́ orí mi kò tó nǹkan rárá, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ojú mi ti rí ọpọlọpọ ibi. Ọjọ́ orí mi kò tíì dé ibìkan lẹ́gbẹ̀ẹ́ ti àwọn baba mi.”

10 Jakọbu súre fún Farao ó sì jáde kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀.

11 Josẹfu bá fi baba ati àwọn arakunrin rẹ̀ sí ibi tí ó dára jùlọ ní ilẹ̀ Ijipti, ninu ilẹ̀ Ramesesi, gẹ́gẹ́ bí Farao ti pa á láṣẹ.

12 Josẹfu pèsè ohun jíjẹ fún baba ati àwọn arakunrin rẹ̀, ati gbogbo àwọn ìdílé baba rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí iye eniyan tí olukuluku wọn ń bọ́.

Àkókò Ìyàn

13 Ìyàn náà mú tóbẹ́ẹ̀ tí ìdààmú bá gbogbo ilẹ̀ Ijipti ati ilẹ̀ Kenaani nítorí pé kò sí oúnjẹ rárá ní ilẹ̀ Kenaani.

14 Gbogbo owó tí àwọn ará ilẹ̀ Ijipti ati àwọn ará ilẹ̀ Kenaani ní patapata ni wọ́n kó tọ Josẹfu wá láti fi ra oúnjẹ. Josẹfu sì kó gbogbo owó náà lọ fún Farao.

15 Nígbà tí kò sí owó mọ́ rárá ní ilẹ̀ Ijipti ati ilẹ̀ Kenaani, gbogbo àwọn ará Ijipti tọ Josẹfu lọ, wọ́n wí pé, “Fún wa ní oúnjẹ. Ǹjẹ́ o lè máa wò wá níran báyìí títí tí a óo fi kú? Kò sí owó lọ́wọ́ wa mọ́ rárá.”

16 Josẹfu bá dá wọn lóhùn pé, “Bí kò bá sí owó lọ́wọ́ yín mọ́, ẹ kó àwọn ẹran ọ̀sìn yín wá, n óo sì fun yín ní oúnjẹ dípò wọn.”

17 Wọ́n bá kó àwọn ẹran ọ̀sìn wọn tọ Josẹfu lọ, Josẹfu sì fún wọn ní oúnjẹ dípò àwọn ẹran ọ̀sìn wọn, agbo ẹran wọn, agbo mààlúù wọn ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn. Ó fi àwọn ẹran ọ̀sìn wọn dí oúnjẹ fún wọn ní ọdún náà.

18 Nígbà tí ọdún náà parí, wọ́n tún wá sọ́dọ̀ Josẹfu ní ọdún keji, wọ́n ní, “A kò jẹ́ purọ́ fún oluwa wa, pé kò sí owó lọ́wọ́ wa mọ́ rárá, gbogbo agbo ẹran wa sì ti di tìrẹ, a kò ní ohunkohun mọ́ àfi ara wa ati ilẹ̀ wa.

19 Ǹjẹ́ o lè máa wò wá níran títí tí a óo fi kú, ati àwa, ati ilẹ̀ wa? Fi oúnjẹ ra àwa ati ilẹ̀ wa, a óo sì di ẹrú Farao. Fún wa ní irúgbìn, kí á lè wà láàyè, kí ilẹ̀ yìí má baà di ahoro.”

20 Josẹfu bá ra gbogbo ilẹ̀ Ijipti fún Farao, nítorí pé gbogbo àwọn ará Ijipti ni wọ́n ta ilẹ̀ wọn, nítorí ìyàn náà dà wọ́n láàmú pupọ. Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo ilẹ̀ Ijipti ṣe di ti Farao,

21 ó sì sọ àwọn eniyan náà di ẹrú rẹ̀ jákèjádò ilẹ̀ Ijipti.

22 Àfi ilẹ̀ àwọn babalóòṣà nìkan ni kò rà, nítorí pé ó ní iye tí Farao máa ń fún wọn nígbàkúùgbà. Ohun tí Farao ń fún wọn yìí ni wọ́n sì fi ń jẹun. Ìdí nìyí tí kò jẹ́ kí wọ́n ta ilẹ̀ wọn.

23 Josẹfu sọ fún àwọn eniyan náà pé, “Àtẹ̀yin, àtilẹ̀ yín, láti òní lọ, mo ra gbogbo yín fún Farao. Irúgbìn nìyí, ẹ lọ gbìn ín sinu oko yín.

24 Nígbà tí ẹ bá kórè, ẹ óo pín gbogbo ohun tí ẹ bá kórè sí ọ̀nà marun-un, ìpín kan jẹ́ ti Farao, ìpín mẹrin yòókù yóo jẹ́ tiyín. Ninu rẹ̀ ni ẹ óo ti mú irúgbìn, ati èyí tí ẹ óo máa jẹ, ẹ̀yin ati gbogbo ìdílé yín pẹlu àwọn ọmọ yín.”

25 Wọ́n dáhùn pé, “Ìwọ ni o gbà wá lọ́wọ́ ikú, bí ó bá ti wù ọ́ bẹ́ẹ̀, a óo di ẹrú Farao.”

26 Bẹ́ẹ̀ ni Josẹfu ṣe sọ ọ́ di òfin ní ilẹ̀ Ijipti, tí ó sì wà títí di òní olónìí pé ìdámárùn-ún gbogbo ìkórè oko jẹ́ ti Farao, ati pé ilẹ̀ àwọn babalóòṣà nìkan ni kì í ṣe ti Farao.

Ẹ̀bẹ̀ tí Jakọbu Bẹ̀ kẹ́yìn

27 Israẹli ń gbé ilẹ̀ Ijipti, ní Goṣeni, wọ́n sì ní ọpọlọpọ ohun ìní níbẹ̀, wọ́n bímọ lémọ, wọ́n sì pọ̀ sí i gidigidi.

28 Ọdún mẹtadinlogun ni Jakọbu gbé sí i ní ilẹ̀ Ijipti, gbogbo ọdún tí ó gbé láyé sì jẹ́ ọdún mẹtadinlaadọjọ (147).

29 Nígbà tí àkókò tí Jakọbu yóo kú súnmọ́ tòsí, ó pe Josẹfu ọmọ rẹ̀, ó wí fún un pé, “Wá, ti ọwọ́ rẹ bọ abẹ́ itan mi, kí o sì ṣèlérí pé o óo ṣe olóòótọ́ sí mi, o kò sì ní dà mí. Má ṣe sin òkú mi sí ilẹ̀ Ijipti,

30 ṣugbọn gbé mi kúrò ní ilẹ̀ Ijipti kí o sì sin mí sí ibojì àwọn baba mi. Ibi tí wọ́n sin wọ́n sí ni mo fẹ́ kí o sin èmi náà sí.”

Josẹfu dáhùn, ó ní, “Mo gbọ́, n óo ṣe bí o ti wí.”

31 Jakọbu ní kí Josẹfu búra fún òun, Josẹfu sì búra fún un. Nígbà náà ni Jakọbu tẹríba lórí ibùsùn rẹ̀.

Categories
JẸNẸSISI

JẸNẸSISI 48

Jakọbu Súre fún Efuraimu ati Manase

1 Lẹ́yìn náà, wọ́n sọ fún Josẹfu pé ara baba rẹ̀ kò yá, Josẹfu bá mú àwọn ọmọ rẹ̀ mejeeji, Manase ati Efuraimu, lọ́wọ́ lọ bẹ baba rẹ̀ wò.

2 Nígbà tí wọ́n sọ fún Jakọbu pé Josẹfu ọmọ rẹ̀ dé, ó ṣe ara gírí, ó jókòó lórí ibùsùn rẹ̀.

3 Jakọbu sọ fún Josẹfu pé, “Ọlọrun Olodumare farahàn mí ní Lusi ní ilẹ̀ Kenaani, ó sì súre fún mi.

4 Ó ní, ‘N óo fún ọ ní ọpọlọpọ ọmọ, n óo sì sọ ọ́ di ọpọlọpọ ẹ̀yà, ati pé àwọn ọmọ ọmọ rẹ ni n óo fi ilẹ̀ náà fún, yóo sì jẹ́ tiwọn títí ayé.’

5 “Tèmi ni àwọn ọmọkunrin mejeeji tí o bí ní ilẹ̀ Ijipti kí n tó dé, bí Reubẹni ati Simeoni ti jẹ́ tèmi, bẹ́ẹ̀ náà ni Manase ati Efuraimu jẹ́ tèmi.

6 Àwọn ọmọ tí o bá tún bí lẹ́yìn wọn, ìwọ ni o ni wọ́n, ninu ogún tí ó bá kan Manase ati Efuraimu ni wọn yóo ti pín.

7 Ìbànújẹ́ ni ó jẹ́ fún mi pé nígbà tí mò ń ti Padani-aramu bọ̀, Rakẹli kú lọ́nà, ní ilẹ̀ Kenaani, ibi tí ó dákẹ́ sí kò jìnnà pupọ sí Efurati. Lójú ọ̀nà Efurati náà ni mo sì sin ín sí.” (Efurati yìí ni wọ́n ń pè ní Bẹtilẹhẹmu.)

8 Nígbà tí Israẹli rí àwọn ọmọ Josẹfu, ó bèèrè pé, “Àwọn wo nìyí?”

9 Josẹfu dá baba rẹ̀ lóhùn, ó ní, “Àwọn ọmọ mi, tí Ọlọrun pèsè fún mi níhìn-ín ni wọ́n.”

Jakọbu bá wí fún un pé, “Jọ̀wọ́, jẹ́ kí wọ́n súnmọ́ mi kí n lè súre fún wọn.”

10 Ogbó ti mú kí ojú Israẹli di bàìbàì ní àkókò yìí, kò sì ríran dáradára mọ́. Josẹfu bá kó wọn súnmọ́ baba rẹ̀, baba rẹ̀ dì mọ́ wọn, ó sì fi ẹnu kò wọ́n lẹ́nu.

11 Ó wí fún Josẹfu pé, “N kò lérò pé mo tún lè fi ojú kàn ọ́ mọ́, ṣugbọn Ọlọrun mú kí ó ṣeéṣe fún mi láti rí àwọn ọmọ rẹ.”

12 Josẹfu bá kó wọn kúrò lẹ́sẹ̀ baba rẹ̀, òun gan-an náà wá dojúbolẹ̀ níwájú baba rẹ̀.

13 Ó fi ọwọ́ ọ̀tún mú Efuraimu, ó fà á súnmọ́ ẹ̀gbẹ́ ọwọ́ òsì baba rẹ̀, ó fi ọwọ́ òsì mú Manase, ó fà á súnmọ́ ẹ̀gbẹ́ ọwọ́ ọ̀tún baba rẹ̀.

14 Ṣugbọn nígbà tí Israẹli na ọwọ́ rẹ̀ láti súre fún wọn, ó dábùú ọwọ́ rẹ̀ lórí ara wọn, ó gbé ọwọ́ ọ̀tún lé Efuraimu lórí, ó sì gbé ọwọ́ òsì lé Manase lórí, bẹ́ẹ̀ ni Efuraimu ni àbúrò, Manase sì ni àkọ́bí.

15 Ó bá súre fún Josẹfu, ó ní,

“Kí Ọlọrun tí Abrahamu ati Isaaki, baba mi, ń sìn bukun àwọn ọmọ wọnyi,

kí Ọlọrun náà tí ó ti ń tọ́ mi ní gbogbo ọjọ́ ayé mi títí di òní yìí bukun wọn,

16 kí angẹli tí ó yọ mí ninu gbogbo ewu bukun wọn;

kí ìrántí orúkọ mi, ati ti Abrahamu, ati ti Isaaki, àwọn baba mi, wà ní ìran wọn títí ayé,

kí atọmọdọmọ wọn pọ̀ lórí ilẹ̀ ayé.”

17 Nígbà tí Josẹfu rí i pé ọwọ́ ọ̀tún ni baba òun gbé lé Efuraimu lórí, kò dùn mọ́ ọn. Ó bá di ọwọ́ baba rẹ̀ mú láti gbé e kúrò lórí Efuraimu kí ó sì gbé e lórí Manase.

18 Ó wí fún baba rẹ̀ pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́, baba, eléyìí ni àkọ́bí, gbé ọwọ́ ọ̀tún rẹ lé e lórí.”

19 Ṣugbọn baba rẹ̀ kọ̀, ó ní, “Mo mọ̀, ọmọ mi, mo mọ̀, òun náà yóo di eniyan, yóo sì di alágbára, ṣugbọn sibẹsibẹ àbúrò rẹ̀ yóo jù ú lọ, àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀ yóo sì di ọpọlọpọ orílẹ̀ èdè.”

20 Ó bá súre fún wọn ní ọjọ́ náà, ó ní,

“Orúkọ yín ni Israẹli yóo fi máa súre fún eniyan,

wọn yóo máa súre pé,

‘Kí Ọlọrun kẹ́ ọ bí ó ti kẹ́ Efuraimu ati Manase.’ ”

Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe fi Efuraimu ṣáájú Manase.

21 Nígbà náà ni Israẹli sọ fún Josẹfu pé, “Àkókò ikú mi súnmọ́ etílé, ṣugbọn Ọlọrun yóo wà pẹlu rẹ, yóo sì mú ọ pada sí ilẹ̀ baba rẹ.

22 Dípò kí n fún àwọn arakunrin rẹ ní Ṣekemu, tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ òkè, níbi tí mo jagun gbà lọ́wọ́ àwọn ará Amori, ìwọ ni mo fún.”

Categories
JẸNẸSISI

JẸNẸSISI 49

Ọ̀rọ̀ Ìkẹyìn Jakọbu

1 Jakọbu ranṣẹ pe àwọn ọmọ rẹ̀, ó wí fún wọn pé, “Ẹ kó ara yín jọ kí n lè sọ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ si yín ní ọjọ́ iwájú fún yín.

2 Ẹ péjọ kí ẹ gbọ́, ẹ̀yin ọmọ Jakọbu,

kí ẹ sì fetí sí ọ̀rọ̀ Israẹli, baba yín.

3 Reubẹni, ìwọ ni àkọ́bí mi,

agbára mi, ati àkọ́so èso agbára mi,

ìwọ tí o ní ìgbéraga jùlọ,

tí o sì lágbára jùlọ ninu àwọn ọmọ mi.

4 Ìwọ tí o dàbí ìkún omi tí ń bì síwá sẹ́yìn,

o kò ní jẹ́ olórí, nítorí pé o ti bá obinrin mi lòpọ̀,

o sì ti sọ ibùsùn èmi baba rẹ di aláìmọ́.

5 Simeoni ati Lefi jẹ́ arakunrin,

ìlò ìkà ati ipá ni wọ́n ń lo idà wọn.

6 Orí mi má jẹ́ kí n bá wọn pa ìmọ̀ pọ̀,

ẹlẹ́dàá mi má sì jẹ́ kí n bá wọn kẹ́gbẹ́.

Nítorí wọn a máa fi ibinu paniyan,

wọn a sì máa ṣá akọ mààlúù lọ́gbẹ́ bí ohun ìdárayá.

7 Ìfibú ni ibinu wọn, nítorí pé ó le,

ati ìrúnú wọn, nítorí ìkà ni wọ́n.

N óo pín wọn káàkiri ilẹ̀ Jakọbu,

n óo sì fọ́n wọn ká ààrin àwọn eniyan Israẹli.

8 Juda, àwọn arakunrin rẹ yóo máa yìn ọ́,

apá rẹ yóo sì ká àwọn ọ̀tá rẹ;

àwọn ọmọ baba rẹ yóo máa tẹríba fún ọ.

9 Juda dàbí kinniun,

tí ó bá pa ohun tí ó ń dọdẹ tán,

a sì tún yan pada sinu ihò rẹ̀.

Tí ó bá nà kalẹ̀, tí ó sì lúgọ,

kò sí ẹni tí ó jẹ́ tọ́ ọ.

10 Ọ̀pá àṣẹ ọba kì yóo kúrò ní ilé Juda,

arọmọdọmọ rẹ̀ ni yóo sì máa jọba,

títí tí yóo fi dé ọ̀dọ̀ ẹni tí ó ni ín;

gbogbo ìran eniyan ni yóo sì máa pa àṣẹ rẹ̀ mọ́.

11 Yóo máa so ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ mọ́ ìtàkùn àjàrà,

yóo so àwọ́nsìn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ mọ́ ìtàkùn àjàrà dáradára,

bẹ́ẹ̀ ni oje àjàrà ni yóo máa fi fọ ẹ̀wù rẹ̀.

12 Ojú rẹ̀ yóo pọ́n fún àmutẹ́rùn ọtí waini,

eyín rẹ̀ yóo sì funfun fún àmutẹ́rùn omi wàrà.

13 “Sebuluni yóo máa gbé etí òkun,

ọkọ̀ ojú omi rẹ̀ kò ní níye,

Sidoni ni yóo jẹ́ ààlà rẹ̀.

14 “Isakari dàbí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí ó lágbára

tí ó dùbúlẹ̀ láàrin gàárì ẹrù rẹ̀.

15 Ṣugbọn nígbà tí ó rí i pé ibi ìsinmi dára

ati pé ilẹ̀ náà dára,

ó tẹ́ ẹ̀yìn sílẹ̀ láti ru ẹrù,

ó sì di ẹni tí wọn ń mú sìn bí ẹrú.

16 Dani ni yóo máa ṣe ìdájọ́ àwọn eniyan rẹ̀,

gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan ninu àwọn ẹ̀yà Israẹli.

17 Dani yóo dàbí ejò lójú ọ̀nà,

ati bíi paramọ́lẹ̀ ní ẹ̀bá ọ̀nà,

tí ń bu ẹṣin ní gìgísẹ̀ jẹ,

kí ẹni tí ó gùn ún lè ṣubú sẹ́yìn.

18 Mo dúró de ìgbàlà rẹ, Oluwa.

19 Àwọn olè yóo máa kó Gadi lẹ́rù,

ṣugbọn bí wọ́n ti ń kó o,

bẹ́ẹ̀ ni yóo sì máa gbà á pada.

20 Aṣeri yóo máa rí oúnjẹ dáradára mú jáde ninu oko rẹ̀,

oúnjẹ ọlọ́lá ni yóo máa ti inú oko rẹ̀ jáde.

21 Nafutali dàbí àgbọ̀nrín tí ń sáré káàkiri,

tí ó sì ní àwọn ọmọ tí ó lẹ́wà.

22 Josẹfu dàbí igi eléso tí ó wà lẹ́bàá odò,

àwọn ẹ̀ka rẹ̀ nà mọ́ ara ògiri.

23 Àwọn tafàtafà gbógun tì í kíkankíkan,

wọ́n ń ta á lọ́fà, wọ́n sì ń dà á láàmú gidigidi,

24 sibẹsibẹ ọrùn rẹ̀ kò mì,

apá rẹ̀ sì ń lágbára sí i.

Agbára Ọlọrun Jakọbu ni ó fún apá rẹ̀ ní okun,

(ní orúkọ Olùṣọ́-aguntan náà,

tí í ṣe Àpáta ààbò Israẹli),

25 Ọlọrun baba rẹ yóo ràn ọ́ lọ́wọ́.

Ọlọrun Olodumare yóo rọ òjò ibukun sórí rẹ láti òkè ọ̀run wá,

yóo sì fún ọ ní ibukun omi tí ó wà ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀,

ati ọpọlọpọ ọmọ ati ọpọlọpọ ẹran ọ̀sìn.

26 Ibukun àwọn baba rẹ ju ti àwọn òkè ayérayé lọ,

kí ibukun àwọn òkè ayérayé wá sórí Josẹfu,

ẹni tí wọ́n yà ní ipá lọ́dọ̀ àwọn arakunrin rẹ̀.

27 “Bẹnjamini dàbí ìkookò tí ebi ń pa,

a máa pa ohun ọdẹ rẹ̀ ní òwúrọ̀,

ati ní àṣáálẹ́ a máa pín ìkógun rẹ̀.”

28 Àwọn ẹ̀yà Israẹli mejeejila ni a ti dárúkọ yìí, ati ohun tí baba wọn wí nígbà tí ó súre fún wọn. Ó súre tí ó tọ́ sí olukuluku fún un.

Ikú Jakọbu ati Ìsìnkú Rẹ̀

29 Jakọbu kìlọ̀ fún wọn, ó ní, “Mo ṣetán, mò ń re ibi àgbà á rè, inú ibojì tí wọ́n sin àwọn baba mi sí, ninu ihò òkúta tí ó wà ninu ilẹ̀ Efuroni, ará Hiti, ni kí ẹ sin mí sí.

30 Ihò òkúta yìí wà ninu pápá ní Makipela, ní ìhà ìlà oòrùn Mamure ní ilẹ̀ Kenaani. Lọ́wọ́ Efuroni ará Hiti ni Abrahamu ti rà á pọ̀ mọ́ ilẹ̀ náà, kí ó lè rí ibi fi ṣe itẹ́ òkú.

31 Níbẹ̀ ni wọ́n sin Abrahamu ati Sara aya rẹ̀ sí, níbẹ̀ náà ni wọ́n sin Isaaki sí ati Rebeka aya rẹ̀, níbẹ̀ ni èmi náà sì sin Lea sí.

32 Lọ́wọ́ àwọn ará Hiti ni wọ́n ti ra ilẹ̀ náà ati ihò òkúta tí ó wà ninu rẹ̀. Níbẹ̀ ni kí ẹ sin mí sí.”

33 Nígbà tí Jakọbu parí ìkìlọ̀ tí ó ń ṣe fún àwọn ọmọ rẹ̀, ó ká ẹsẹ̀ rẹ̀ pada sí orí ibùsùn rẹ̀, ó dùbúlẹ̀, lẹ́yìn náà ó mí kanlẹ̀, ó sì re ibi tí àgbà á rè.