Categories
ÌWÉ ÒWE

ÌWÉ ÒWE 30

Àwọn Ọ̀rọ̀ tí Aguri sọ

1 Ọ̀rọ̀ Aguri, ọmọ Jake ará Masa nìyí:

Ọkunrin yìí sọ fún Itieli ati Ukali pé,

2 “Nítòótọ́ mo jẹ́ aláìmọ̀kan jùlọ ninu gbogbo eniyan,

n kò ní òye tí ó yẹ kí eniyan ní.

3 N kò tíì kọ́ ọgbọ́n,

n kò sì ní ìmọ̀ Ẹni Mímọ́.

4 Ta ló ti lọ sí ọ̀run rí, tí ó sì tún pada wá?

Ta ló ti kó afẹ́fẹ́ jọ sí ọwọ́ rẹ̀?

Ta ló ti fi aṣọ rẹ̀ di omi?

Ta ló fi ìdí gbogbo òpin ayé múlẹ̀?

Kí ni orúkọ olúwarẹ̀? Kí sì ni orúkọ ọmọ rẹ̀?

Ṣé o mọ̀ ọ́n!

5 Kò sí ọ̀rọ̀ Ọlọrun kankan tí ó ń yẹ̀,

òun ni ààbò fún àwọn tí wọ́n wá ààbò lọ sọ́dọ̀ rẹ̀.

6 Má fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀,

kí ó má baà bá ọ wí,

kí o má baà di òpùrọ́.”

Àwọn Òwe Mìíràn

7 Nǹkan meji ni mò ń tọrọ lọ́wọ́ rẹ,

má ṣe fi wọ́n dù mí kí n tó kú.

8 Jẹ́ kí ìwà èké ati irọ́ pípa jìnnà sí mi,

má jẹ́ kí n talaka, má sì jẹ́ kí n di ọlọ́rọ̀,

fún mi ní ìwọ̀nba oúnjẹ tí ó tó mi jẹ,

9 kí n má baà yó tán, kí n sẹ́ ọ,

kí n wí pé, “Ta ni ń jẹ́ OLUWA?”

Má sì jẹ́ kí n tòṣì, kí n má baà jalè,

kí n sì kó ẹ̀gbin bá orúkọ Ọlọrun.

10 Má ba iranṣẹ jẹ́ lójú ọ̀gá rẹ̀,

kí ó má baà gbé ọ ṣépè, kí o sì di ẹlẹ́bi.

11 Àwọn kan wà tí wọn ń gbé baba wọn ṣépè,

tí wọn kò sì súre fún ìyá wọn.

12 Àwọn tí wọ́n mọ́ lójú ara wọn,

ṣugbọn a kò tíì wẹ èérí wọn nù.

13 Àwọn kan wà tí ojú wọ́n ga,

lókè lókè ni ojú wọn wà.

14 Àwọn kan wà tí eyín wọn dàbí idà,

kìkì ọ̀bẹ ló kún èrìgì wọn,

láti jẹ àwọn talaka run lórí ilẹ̀ ayé,

ati láti pa àwọn aláìní run láàrin àwọn eniyan.

15 Eṣúṣú bí ọmọbinrin meji, ó sì sọ àwọn mejeeji ni:

“Mú wá, Mú wá.”

Àwọn nǹkan pupọ wà tí kì í ní ìtẹ́lọ́rùn,

wọ́n pọ̀ tí nǹkan kìí tó:

16 isà òkú ati inú àgàn,

ilẹ̀ tí ń pòùngbẹ omi ati iná,

wọn kì í sọ pé, “Ó tó.”

17 Ẹni tí ń fi baba rẹ̀ ṣe yẹ̀yẹ́,

tí ó kọ̀ tí kò tẹríba fún ìyá rẹ̀,

ẹyẹ ìwò àfonífojì ati àwọn igún ni yóo yọ ojú rẹ̀ jẹ.

18 Àwọn nǹkankan wà tí ń jọ mí lójú,

àwọn nǹkan mẹrin kò yé mi:

19 ipa ẹyẹ idì ní ojú ọ̀run,

ipa ejò lórí àpáta,

ọ̀nà tí ọkọ̀ ń tọ̀ lójú òkun,

ati nǹkan tí ń bẹ láàrin ọkunrin ati obinrin.

20 Ìwà obinrin alágbèrè nìyí:

bí ó bá ṣe àgbèrè tán, á ṣojú fúrú,

á ní “N kò ṣe àìdára kankan.”

21 Àwọn nǹkankan wà tíí mi ilẹ̀ tìtì,

ọ̀pọ̀ nǹkan wà tí ilẹ̀ kò lè gbà mọ́ra:

22 ẹrú tí ó jọba,

òmùgọ̀ tí ó jẹun yó,

23 obinrin tí ayé kórìíra tí ó wá rí ọkọ fẹ́,

ati iranṣẹbinrin tí ó gba ọkọ mọ́ ọ̀gá rẹ̀ lọ́wọ́.

24 Àwọn nǹkan mẹrin kan wà tí wọ́n kéré ninu ayé,

sibẹsibẹ wọ́n gbọ́n lọpọlọpọ:

25 àwọn èèrà kò lágbára,

ṣugbọn wọn a máa kó oúnjẹ wọn jọ ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn.

26 Àwọn ehoro ìgbẹ́ kò lágbára,

sibẹsibẹ wọ́n ń kọ́ ilé sí pàlàpálá òkúta.

27 Àwọn eṣú kò ní ọba,

sibẹsibẹ wọ́n ń rìn ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́.

28 Eniyan lè fi ọwọ́ mú aláǹgbá,

sibẹsibẹ wọ́n pọ̀ ní ààfin ọba.

29 Àwọn nǹkan mélòó kan wà tí ìrìn yẹ,

àwọn nǹkan pọ̀ tí ìrìn ẹsẹ̀ wọn máa ń wu eniyan:

30 Kinniun, alágbára jùlọ láàrin àwọn ẹranko,

kì í sì í sá fún ẹnikẹ́ni.

31 Àkùkọ gàgàrà ati ẹran òbúkọ,

ati ọba tí ń yan níwájú àwọn eniyan rẹ̀.

32 Bí o bá ti ń hùwà òmùgọ̀, tí ò ń gbé ara rẹ ga,

tabi tí o tí ń gbèrò ibi,

fi òpin sí i, kí o sì ronú.

33 Bí a bá po wàrà pọ̀ títí, yóo di òrí àmọ́,

bí ó bá pẹ́ tí a ti ń tẹ imú, imú yóo ṣẹ̀jẹ̀,

bẹ́ẹ̀ ni ríru ibinu sókè, a máa mú ìjà wá!

Categories
ÌWÉ ÒWE

ÌWÉ ÒWE 31

Ìmọ̀ràn fún Ọba

1 Èyí ni ọ̀rọ̀ Lemueli, ọba Masa, tí ìyá rẹ̀ kọ́ ọ:

2 Ìwọ ni ọmọ mi, ọmọ bíbí inú mi,

ìwọ ni ọmọ tí mo jẹ́jẹ̀ẹ́ bí.

3 Má ṣe lo agbára rẹ lórí obinrin,

má fi ọ̀nà rẹ lé àwọn tí wọn ń pa ọba run lọ́wọ́.

4 Gbọ́, ìwọ Lemueli,

ọba kò gbọdọ̀ máa mu ọtí,

àwọn aláṣẹ kò sì gbọdọ̀ máa wá ọtí líle.

5 Kí wọn má baà mu ún tán, kí wọn gbàgbé òfin,

kí wọn sì yí ìdájọ́ ẹni tí ojú ń pọ́n po.

6 Fún ẹni tí ń ṣègbé lọ ní ọtí mu,

fún àwọn tí ọkàn wọ́n bàjẹ́ ní ọtí líle,

7 jẹ́ kí wọn mu ún, kí wọn gbàgbé òṣì wọn,

kí wọn má sì ranti ìnira wọn mọ́.

8 Gba ẹjọ́ àwọn tí kò ní ẹnu ọ̀rọ̀ rò,

ati ti àwọn tí a sọ di aláìní.

9 Má dákẹ́, kí o ṣe ìdájọ́ òdodo,

bá talaka ati aláìní gba ẹ̀tọ́ wọn.

Iyawo tí Ó Ní Ìwà Rere

10 Ta ló lè rí iyawo tí ó ní ìwà rere fẹ́?

Ó ṣọ̀wọ́n ju ohun ọ̀ṣọ́ olówó iyebíye lọ.

11 Ọkọ rẹ̀ yóo fi tọkàntọkàn gbẹ́kẹ̀lé e,

kò sì ní ṣaláì ní ohunkohun.

12 Rere ni obinrin náà máa ń ṣe fún un

kò ní ṣe é níbi, ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.

13 A máa lọ wá irun aguntan ati òwú ìhunṣọ,

a sì máa fi tayọ̀tayọ̀ hun aṣọ.

14 Obinrin náà dàbí ọkọ̀ ojú omi oníṣòwò,

tí ó ń mú oúnjẹ wálé láti ọ̀nà jíjìn réré.

15 Ìdájí níí tií jí láti wá oúnjẹ fún ìdílé rẹ̀,

ati láti yan iṣẹ́ fún àwọn iranṣẹbinrin rẹ̀.

16 Bí ó bá rí ilẹ̀ oko, a yẹ̀ ẹ́ wò, a sì rà á,

a sì fi èrè iṣẹ́ rẹ̀ gbin ọgbà àjàrà.

17 A fi agbára fún ọ̀já mọ́nú,

a sì tẹpá mọ́ṣẹ́.

18 A máa mójútó ọjà tí ó ń tà,

fìtílà rẹ̀ kì í sì í kú lóru.

19 Ó fi ọwọ́ lé kẹ̀kẹ́ òwú,

ó sì ń ran òwú.

20 Ó lawọ́ sí àwọn talaka,

a sì máa ran àwọn aláìní lọ́wọ́.

21 Kì í bẹ̀rù nítorí ìdílé rẹ̀ nígbà òtútù,

nítorí gbogbo wọn ni ó ti bá hun aṣọ tí ó móoru.

22 A máa hun aṣọ ọlọ́nà a sì fi bo ibùsùn rẹ̀,

òun náà á wọ aṣọ funfun dáradára ati ti elése àlùkò.

23 Wọ́n dá ọkọ rẹ̀ mọ̀ lẹ́nu ibodè,

nígbà tí ó bá jókòó pẹlu àwọn àgbààgbà ìlú.

24 A máa hun aṣọ funfun, a sì tà wọ́n,

a máa ta ọ̀já ìgbànú fún àwọn oníṣòwò.

25 Agbára ati ọlá ni ó fi ń bora bí aṣọ,

ó sì ní ìrètí ayọ̀ nípa ọjọ́ iwájú.

26 Ọ̀rọ̀ ọgbọ́n ní ń jáde láti ẹnu rẹ̀,

a sì máa kọ́ni ní ẹ̀kọ́ àánú.

27 A máa ṣe ìtọ́jú ìdílé rẹ̀ dáradára,

kì í sì í hùwà ọ̀lẹ.

28 Àwọn ọmọ rẹ̀ a máa pè é ní ẹni ibukun,

ọkọ rẹ̀ pẹlu a sì máa yìn ín pé,

29 “Ọpọlọpọ obinrin ni wọ́n ti ṣe ribiribi,

ṣugbọn ìwọ ta gbogbo wọn yọ.”

30 Ẹ̀tàn ni ojú dáradára, asán sì ni ẹwà,

obinrin tí ó bá bẹ̀rù OLUWA ni ó yẹ kí á yìn.

31 Fún un ninu èrè iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀,

jẹ́ kí wọn máa yìn ín lẹ́nu ibodè nítorí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.