Categories
ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ

ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 10

1 Bí òkú eṣinṣin ṣe lè ba òórùn turari jẹ́;

bẹ́ẹ̀ ni ìwà òmùgọ̀ kékeré lè ba ọgbọ́n ńlá ati iyì jẹ́.

2 Ọkàn ọlọ́gbọ́n eniyan a máa darí rẹ̀ sí ọ̀nà rere,

ṣugbọn ọ̀nà burúkú ni ọkàn òmùgọ̀ ń darí rẹ̀ sí.

3 Ìrìn ẹsẹ̀ òmùgọ̀ láàrin ìgboro ń fihàn pé kò gbọ́n,

a sì máa fihan gbogbo eniyan bí ó ti gọ̀ tó.

4 Bí aláṣẹ bá ń bínú sí ọ,

má ṣe torí rẹ̀ kúrò ní ìdí iṣẹ́ rẹ,

ìtẹríba lè mú kí wọn dárí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó bá tóbi jini.

5 Nǹkan burúkú tí mo tún rí láyé ni, irú àṣìṣe tí àwọn aláṣẹ pàápàá ń ṣe:

6 Wọ́n fi àwọn òmùgọ̀ sí ipò gíga, nígbà tí àwọn ọlọ́rọ̀ wà ní ipò tí ó rẹlẹ̀.

7 Mo rí i tí àwọn ẹrú ń gun ẹṣin, nígbà tí àwọn ọmọ-aládé ń fẹsẹ̀ rìn bí ẹrú.

8 Ẹni tí ó gbẹ́ kòtò ni yóo jìn sinu rẹ̀,

ẹni tí ó bá já ọgbà wọlé ni ejò yóo bùjẹ.

9 Ẹni tí ó bá ń fọ́ òkúta, ni òkúta í pa lára;

ẹni tí ó bá ń la igi, ni igi í ṣe ní jamba.

10 Ẹni tí kò bá pọ́n àáké rẹ̀ kí ó mú,

yóo lo agbára pupọ bí ó bá fẹ́ lò ó,

ṣugbọn ọgbọ́n a máa ranni lọ́wọ́ láti ṣe àṣeyọrí.

11 Lẹ́yìn tí ejò bá ti buni jẹ tán,

kò ṣàǹfààní mọ́ kí á máa pọfọ̀ sí ejò.

12 Ọ̀rọ̀ ẹnu ọlọ́gbọ́n a máa bu iyì kún un,

ṣugbọn ẹnu òmùgọ̀ ni yóo pa á.

13 Agọ̀ ni ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀,

wèrè sì ni ìparí rẹ̀.

14 Òmùgọ̀ ń sọ̀rọ̀ láìdákẹ́,

kò sí ẹni tí ó mọ ohun tí ń bọ̀ lẹ́yìn ọ̀la,

ta ni lè sọ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀ fún un.

15 Làálàá ọ̀lẹ ń kó àárẹ̀ bá a,

tóbẹ́ẹ̀ tí kò mọ ọ̀nà ìlú mọ́.

16 Ilẹ̀ tí ọba rẹ̀ jẹ́ ọmọde gbé!

Tí àwọn olórí rẹ̀ ń ṣe àríyá láàárọ̀.

17 Ilẹ̀ tí ọba rẹ̀ kì í bá ṣe ọmọ ẹrú ṣoríire!

Tí àwọn olórí rẹ̀ ń ṣe àríyá ní àsìkò tí ó tọ́;

tí wọn ń jẹ tí wọn ń mu kí wọn lè lágbára,

ṣugbọn tí kì í ṣe fún ìmutípara.

18 Ọ̀lẹ a máa jẹ́ kí ilé ẹni wó,

ìmẹ́lẹ́ a máa jẹ́ kí ilé ẹni jò.

19 Oúnjẹ a máa múni rẹ́rìn-ín,

waini a sì máa mú inú ẹni dùn,

ṣugbọn owó ni ìdáhùn ohun gbogbo.

20 Má bú ọba, kì báà jẹ́ ninu ọkàn rẹ,

má sì gbé ọlọ́rọ̀ ṣépè, kì báà jẹ́ ninu yàrá rẹ,

nítorí atẹ́gùn lè gbé ọ̀rọ̀ rẹ lọ,

tabi kí àwọn ẹyẹ kan lọ ṣòfófó rẹ.

Categories
ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ

ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 11

Nǹkan Tí Ọlọ́gbọ́n Eniyan Ń Ṣe

1 Gbin nǹkan ọ̀gbìn káàkiri lọpọlọpọ, o óo sì kórè ọpọlọpọ èso nígbà tó bá yá.

2 Gbin àwọn kan síhìn-ín, gbin àwọn kan sọ́hùn-ún, gbìn ín káàkiri oko nítorí o kò mọ ohun tí ó lè ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ọ̀la.

3 Nígbà tí òjò bá ṣú dẹ̀dẹ̀, orí ilẹ̀ ni yóo rọ̀ sí, níbi tí igi bá wó sí, níbẹ̀ náà ni yóo wà.

4 Ẹni tí ń wo ojú afẹ́fẹ́ kò ní fún irúgbìn kankan,

ẹni tí ó bá sì ń wo ṣúṣú òjò kò ní kórè.

5 Gẹ́gẹ́ bí o kò ti mọ bí ẹ̀mí ṣe ń wọ inú ọmọ ninu aboyún, bẹ́ẹ̀ ni o kò mọ̀ bí Ọlọrun ṣe dá ohun gbogbo.

6 Fún irúgbìn ní àárọ̀, má sì ṣe dáwọ́ dúró ní ìrọ̀lẹ́, nítorí o kò mọ èyí tí yóo dàgbà, bóyá ti òwúrọ̀ ni tabi ti ìrọ̀lẹ́, tabi àwọn mejeeji.

7 Ìmọ́lẹ̀ dára, oòrùn sì dùn-ún wò.

8 Bí eniyan ti wù kí ó pẹ́ láyé tó, kí ó máa yọ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀, ṣugbọn kí ó ranti pé ọjọ́ tí òun yóo lò ninu ibojì yóo pọ̀ ju èyí tí òun yóo lò láyé lọ. Asán ni ìgbẹ̀yìn gbogbo ohun tí ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀.

Ìmọ̀ràn fún Àwọn Ọ̀dọ́

9 Ìwọ ọdọmọkunrin, máa yọ̀ ní ìgbà èwe rẹ, kí inú rẹ máa dùn; máa ṣe bí ọkàn rẹ ti ń fẹ́, ati bí ó ti tọ́ lójú rẹ. Ṣugbọn ranti pé, Ọlọrun yóo ṣe ìdájọ́ gbogbo ohun tí o bá ṣe.

10 Gbé ìbànújẹ́ kúrò lọ́kàn rẹ, má sì gba ìrora láàyè lára rẹ, nítorí asán ni ìgbà èwe ati ìgbà ọmọde.

Categories
ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ

ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 12

1 Ranti ẹlẹ́dàá rẹ ní ìgbà èwe rẹ, kí ọjọ́ ibi tó dé, kí ọjọ́ ogbó rẹ tó súnmọ́ etílé, nígbà tí o óo wí pé, “N kò ní inú dídùn ninu wọn.”

2 Kí oòrùn ati ìmọ́lẹ̀ ati òṣùpá ati ìràwọ̀ tó ṣókùnkùn, kí ìkùukùu tó pada lẹ́yìn òjò;

3 nígbà tí àwọn tí ń ṣọ́ ilé yóo máa gbọ̀n pẹ̀pẹ̀, tí ẹ̀yìn àwọn alágbára yóo tẹ̀, tí àwọn òòlọ̀ yóo dákẹ́ jẹ́ẹ́, nítorí pé wọn kò pọ̀ mọ́, tí àwọn tí ń wo ìta láti ojú fèrèsé yóo máa ríran bàìbàì;

4 tí àwọn ìlẹ̀kùn yóo tì ní ìgboro, tí ariwo òòlọ̀ yóo rọlẹ̀, tí ohùn ẹyẹ lásán yóo máa jí eniyan kalẹ̀, tí àwọn ọdọmọbinrin tí wọn ń kọrin yóo dákẹ́;

5 ẹ̀rù ibi gíga yóo máa bani, ìbẹ̀rù yóo sì wà ní ojú ọ̀nà; tí igi alimọndi yóo tanná, tí tata yóo rọra máa wọ́ ẹsẹ̀ lọ, tí ìfẹ́ ọkàn kò ní sí mọ́, nítorí pé ọkunrin ń lọ sí ilé rẹ̀ ayérayé, àwọn eniyan yóo sì máa ṣọ̀fọ̀ kiri láàrin ìgboro;

6 kí ẹ̀wọ̀n fadaka tó já, kí àwo wúrà tó fọ́; kí ìkòkò tó fọ́ níbi orísun omi, kí okùn ìfami tó já létí kànga;

7 kí erùpẹ̀ tó pada sí ilẹ̀ tí ó wà tẹ́lẹ̀, kí ẹ̀mí tó pada tọ Ọlọrun tí ó fúnni lọ.

8 Asán ninu asán, ọ̀jọ̀gbọ́n ní, asán ni gbogbo rẹ̀.

Kókó Gbogbo Ọ̀rọ̀ náà

9 Yàtọ̀ sí pé ọ̀jọ̀gbọ́n náà gbọ́n, ó tún kọ́ àwọn eniyan ní ìmọ̀. Ó wádìí àwọn òwe fínnífínní, ó sì tò wọ́n lẹ́sẹẹsẹ.

10 Ó wádìí ọ̀rọ̀ tí ó tuni lára ati ọ̀rọ̀ òdodo, ó sì kọ wọ́n sílẹ̀ pẹlu òtítọ́ ọkàn.

11 Ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n dàbí ẹ̀gún, bẹ́ẹ̀ ni àkójọ òwe tí olùṣọ́-aguntan kan bá sọ dàbí ìṣó tí a kàn tí ó dúró gbọningbọnin.

12 Ọmọ mi, ṣọ́ra fún ohunkohun tí ó bá kọjá eléyìí, ìwé kíkọ́ kò lópin, àkàjù ìwé a sì máa kó àárẹ̀ bá eniyan.

13 Kókó gbogbo ọ̀rọ̀ náà ni ohun tí a ti gbọ́ tẹ́lẹ̀ pé, bẹ̀rù Ọlọrun, kí o sì pa òfin rẹ̀ mọ́, nítorí èyí nìkan ni iṣẹ́ ọmọ eniyan.

14 Nítorí Ọlọrun yóo mú gbogbo nǹkan tí eniyan bá ṣe wá sí ìdájọ́, ati gbogbo nǹkan àṣírí, ìbáà ṣe rere tabi burúkú.