Categories
ISIKIẸLI

ISIKIẸLI 30

OLUWA Yóo Jẹ Ijipti Níyà

1 OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní,

2 “Ìwọ ọmọ eniyan, sọ àsọtẹ́lẹ̀ kí o sì wí pé, OLUWA Ọlọrun ní,

3 ‘Ẹ sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn nítorí ọjọ́ burúkú tí ń bọ̀,

nítorí ọjọ́ náà súnmọ́lé,

ọjọ́ OLUWA ti dé tán,

yóo jẹ́ ọjọ́ ìṣúdudu

ati ìparun fún àwọn orílẹ̀-èdè.

4 Ogun yóo jà ní Ijipti,

ìrora yóo sì bá Etiopia.

Nígbà tí ọpọlọpọ òkú bá sùn ní Ijipti,

tí a kó ọrọ̀ rẹ̀ lọ,

tí a sì wó ìpìlẹ̀ rẹ̀ lulẹ̀.

5 “ ‘Àwọn ará Etiopia, ati Puti, ati Ludi, ati gbogbo ilẹ̀ Arabia ati Libia, ati gbogbo àwọn eniyan wa tí wọ́n jọ gbìmọ̀ pọ̀, ni ogun yóo pa.’ ”

6 OLUWA ní, “Àwọn tí ń ran Ijipti lọ́wọ́ yóo ṣubú,

ìgbéraga rẹ̀ yóo sì wálẹ̀;

láti Migidoli títí dé Siene,

wọn ó kú ikú ogun láàrin ìlú.

Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

7 “Ijipti óo di ahoro patapata àwọn ìlú rẹ̀ yóo wà lára àwọn ìlú tí yóo tú patapata.

8 Wọn yóo mọ̀ pé èmi ni OLUWA nígbà tí mo bá dáná sun Ijipti, tí gbogbo àwọn olùrànlọ́wọ́ rẹ̀ bá ṣubú.

9 “Nígbà tó bá tó àkókò, n óo rán àwọn ikọ̀ ninu ọkọ̀ ojú omi, wọn ó lọ dẹ́rù ba àwọn ará Etiopia tí wọn ń gbé láìfura. Wahala yóo dé bá àwọn ará Etiopia ní ọjọ́ ìparun Ijipti. Wò ó, ìparun náà ti dé tán.”

10 OLUWA Ọlọrun ní, “N óo ti ọwọ́ Nebukadinesari, ọba Babiloni, fi òpin sí ọrọ̀ Ijipti.

11 Òun ati àwọn eniyan rẹ̀, tí wọ́n jẹ́ orílẹ̀-èdè oníjàgídíjàgan jùlọ ni, yóo wá pa ilẹ̀ Ijipti run, wọn yóo yọ idà ti Ijipti, ọpọlọpọ yóo sì kú ní ilẹ̀ náà.

12 N óo mú kí odò Naili gbẹ, n óo ta ilẹ̀ náà fún àwọn eniyan burúkú; n óo sì jẹ́ kí àwọn àjèjì sọ ilẹ̀ náà ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀ di ahoro. Èmi OLUWA ní mo sọ bẹ́ẹ̀.”

13 OLUWA Ọlọrun ní, “N óo fọ́ àwọn ère tí ó wà ní Memfisi, n óo sì pa wọ́n run. Kò ní sí ọba ní ilẹ̀ Ijipti mọ́, n óo jẹ́ kí ìbẹ̀rù dé bá ilẹ̀ Ijipti.

14 N óo sọ Patirosi di ahoro, n óo sì dáná sun Soani, n óo sì ṣe ìdájọ́ fún ìlú Tebesi.

15 N óo bínú sí Pelusiumu, ibi ààbò Ijipti, n óo sì pa ogunlọ́gọ̀ àwọn tí ń gbé Tebesi.

16 N óo dáná sun Ijipti, Pelusiumu yóo sì wà ninu ìrora ńlá.

17 N óo fi idà pa àwọn ọdọmọkunrin Oni ati ti Pibeseti; a óo sì kó àwọn obinrin wọn lọ sí ìgbèkùn.

18 Ojú ọjọ́ yóo ṣókùnkùn ní Tehafinehesi nígbà tí mo bá ṣẹ́ ọ̀pá ìjọba Ijipti, agbára tí ó ń gbéraga sí yóo sì dópin. Ìkùukùu óo bò ó mọ́lẹ̀; wọn óo sì kó àwọn ọmọbinrin rẹ̀ lọ sí ìgbèkùn.

19 Bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe ṣe ìdájọ́ Ijipti, wọn óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA.”

A Ṣẹ́ Agbára Ọba Ijipti

20 Ní ọjọ́ keje, oṣù kinni ọdún kọkanla, OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní,

21 “Ìwọ ọmọ eniyan, mo ti ṣẹ́ Farao, ọba Ijipti, lápá, a kò sì tíì dí i, kí ọgbẹ́ rẹ̀ fi san, kí ó sì fi lágbára láti gbá idà mú.

22 Nítorí náà, mo lòdì sí Farao, ọba Ijipti. Èmi OLUWA Ọlọrun ní mo sọ bẹ́ẹ̀. N óo ṣẹ́ ẹ ní apá mejeeji: ati èyí tó ṣì lágbára, ati èyí tí ó ti ṣẹ́ tẹ́lẹ̀; n óo sì gbọn idà bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀.

23 N óo fọ́n àwọn ará Ijipti ká orílẹ̀-èdè ayé, n óo sì tú wọn káàkiri gbogbo ilẹ̀ ayé.

24 N óo fún ọba Babiloni lágbára, n óo sì fi idà mi lé e lọ́wọ́; ṣugbọn n óo ṣẹ́ Farao lápá; yóo máa kérora níwájú rẹ̀ bí ẹni tí a ṣá lọ́gbẹ́ tí ó ń kú lọ.

25 N óo fún ọba Babiloni lágbára, ṣugbọn ọwọ́ Farao yóo rọ. Wọn yóo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA. Nígbà tí mo bá fi idà mi lé ọba Babiloni lọ́wọ́, yóo fa idà náà yọ yóo gbógun ti ilẹ̀ Ijipti.

26 N óo fọ́n àwọn ará Ijipti ká sáàrin àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, n óo sì tú wọn káàkiri gbogbo ilẹ̀ ayé. Wọn óo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA.”

Categories
ISIKIẸLI

ISIKIẸLI 31

A Fi Ijipti Wé Igi Kedari

1 Ní ọjọ́ kinni, oṣù kẹta, ọdún kọkanla tí a ti wà ní ìgbèkùn, OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní,

2 “Ìwọ ọmọ eniyan, sọ fún Farao, ọba Ijipti, pẹlu ogunlọ́gọ̀ àwọn eniyan rẹ̀ pé,

Ta ni ó lágbára tó ọ?

3 Wò ó! Mo fi ọ́ wé igi kedari Lẹbanoni,

àwọn ẹ̀ka rẹ̀ lẹ́wà,

wọ́n sì ní ìbòòji ó ga fíofío,

orí rẹ̀ sì kan ìkùukùu lójú ọ̀run.

4 Omi mú kí ó dàgbà,

ibú omi sì mú kí ó ga.

Ó ń mú kí àwọn odò rẹ̀ ṣàn yí ibi tí a gbìn ín sí ká.

Ó ń mú kí odò rẹ̀ ṣàn lọ síbi gbogbo igi igbó.

5 Nítorí náà, ó ga sókè fíofío, ju gbogbo igi inú igbó lọ.

Àwọn ẹ̀ka rẹ̀ tóbi, wọ́n sì gùn,

nítorí ọpọlọpọ omi tí ó ń rí.

6 Gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run, pa ìtẹ́ sára àwọn ẹ̀ka rẹ̀.

Lábẹ́ rẹ̀ ni gbogbo ẹranko inú igbó ń bímọ sí.

Gbogbo orílẹ̀-èdè ńláńlá sì fi ìbòòji abẹ́ rẹ̀ ṣe ibùgbé.

7 Ó tóbi, ó lọ́lá ẹ̀ka rẹ̀ sì lẹ́wà

nítorí pé gbòǹgbò rẹ̀ wọ ilẹ̀ lọ,

ó sì kan ọpọlọpọ omi nísàlẹ̀ ilẹ̀.

8 Igi kedari tí ó wà ninu ọgbà Ọlọrun kò lè farawé e.

Bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀ka igi firi kò sì tó ẹ̀ka rẹ̀.

Ẹ̀ka igi kankan kò dàbí ẹ̀ka rẹ̀,

bẹ́ẹ̀ ni kò sí igikígi ninu ọgbà Ọlọrun tí ó lẹ́wà bíi rẹ̀.

9 Mo dá a ní arẹwà, pẹlu ẹ̀ka tí ó pọ̀.

Gbogbo igi ọgbà Edẹni,

tí ó wà ninu ọgbà Ọlọrun sì ń jowú rẹ̀.

10 “Nítorí pé ó ga sókè fíofío, góńgó orí rẹ̀ wọ inú ìkùukùu lójú ọ̀run, ọkàn rẹ̀ sì kún fún ìgbéraga nítorí gíga rẹ̀.

11 N óo fi lé ẹni tí ó lágbára jù láàrin àwọn orílẹ̀-èdè lọ́wọ́, yóo sì ṣe é fún un gẹ́gẹ́ bí ìwà ìkà rẹ̀. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀. N óo lé e jáde.

12 Àwọn àjèjì láti inú orílẹ̀-èdè, tí ó burú jùlọ, yóo gé e lulẹ̀, wọn yóo sì fi í sílẹ̀. Àwọn ẹ̀ka rẹ̀ yóo bọ́ sílẹ̀ lórí àwọn òkè ati ní àwọn àfonífojì, igi rẹ̀ yóo sì wà nílẹ̀ káàkiri ní gbogbo ipadò ilẹ̀ náà. Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yóo kúrò lábẹ́ òjìji rẹ̀, wọn yóo sì fi sílẹ̀.

13 Gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run yóo kọ́lé sórí ìtì igi rẹ̀ tí ó wó lulẹ̀. Gbogbo ẹranko inú igbó yóo tẹ àwọn ẹ̀ka rẹ̀ mọ́lẹ̀.

14 Gbogbo èyí yóo ṣẹlẹ̀ kí igi mìíràn tí ó bá wà lẹ́bàá omi náà má baà ga fíofío mọ́, tabi kí orí rẹ̀ wọ inú ìkùukùu ní ojú ọ̀run. Kò sì ní sí igi tí ń fa omi, tí yóo ga tó ọ; nítorí gbogbo wọn ni wọn óo kú, tí wọn óo sì lọ sí ìsàlẹ̀ ọ̀gbun ilẹ̀ bí àwọn alààyè eniyan tí wọ́n ti lọ sí ipò òkú.”

15 OLUWA Ọlọrun ní: “Nígbà tí ó bá wọ isà òkú ọ̀gbun ilẹ̀ pàápàá, n óo ṣọ̀fọ̀ rẹ̀, n óo sé àwọn odò n óo sì ti orísun omi ìsàlẹ̀ ilẹ̀ nítorí rẹ̀, òkùnkùn óo bo Lẹbanoni, gbogbo igi inú igbó yóo gbẹ nítorí rẹ̀.

16 Ìró wíwó rẹ̀ yóo mi àwọn orílẹ̀-èdè tìtì. Nígbà tí mo bá wó o lulẹ̀ tí mo bá sọ ọ́ sinu isà òkú pẹlu àwọn tí wọ́n ti lọ sí ipò òkú; gbogbo àwọn igi Edẹni, ati àwọn igi tí wọ́n dára jù ní Lẹbanoni, gbogbo àwọn igi tí ń rí omi mu lábẹ́ ilẹ̀ ni ara yóo tù.

17 Àwọn náà yóo lọ sí ipò òkú pẹlu rẹ̀, sọ́dọ̀ àwọn tí wọ́n fi idà pa; àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti ń gbé abẹ́ òjìji rẹ̀ yóo sì parun.

18 “Ògo ati títóbi ta ni a lè fi wé tìrẹ láàrin àwọn igi tí ó wà ní Edẹni? Ṣugbọn a óo gé ọ lulẹ̀ pẹlu àwọn igi ọgbà Edẹni, a óo sì wọ́ ọ sọ sí ìsàlẹ̀ ilẹ̀. O óo wà nílẹ̀ láàrin àwọn aláìkọlà,pẹlu àwọn tí a fi idà pa. Farao ati ogunlọ́gọ̀ àwọn eniyan rẹ̀ ni mò ń sọ nípa wọn. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

Categories
ISIKIẸLI

ISIKIẸLI 32

A Fi Ọba Ijipti Wé Diragoni

1 Ní ọjọ́ kinni oṣù kejila, ọdún kejila tí a ti wà ní ìgbèkùn, OLUWA bá mi sọ̀rọ̀.

2 Ó ní, “Ìwọ ọmọ eniyan, gbé ohùn sókè kí o kọ orin arò nípa Farao, ọba Ijipti. Wí fún un pé ó ka ara rẹ̀ kún kinniun láàrin àwọn orílẹ̀-èdè. Ṣugbọn ó dàbí diragoni ninu omi. Ó ń jáde tagbára tagbára láti inú odò, ó ń fẹsẹ̀ da omi rú, ó sì ń dọ̀tí àwọn odò.

3 Sọ pé èmi, OLUWA Ọlọrun ní n óo da àwọ̀n mi bò ó níṣojú ogunlọ́gọ̀ àwọn eniyan; wọn óo sì fi àwọ̀n mi wọ́ ọ sókè.

4 N óo wọ́ ọ jù sórí ilẹ̀; inú pápá ni n óo sọ ọ́ sí, n óo jẹ́ kí gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run pa ìtẹ́ wọn lé e lórí. N óo sì jẹ́ kí àwọn ẹranko ilẹ̀ ayé jẹ ẹran ara rẹ.

5 N óo sọ ẹran ara rẹ̀ káàkiri sí orí àwọn òkè. N óo sì fi òkú rẹ̀ kún àwọn àfonífojì.

6 N óo tú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ dà sórí ilẹ̀ ati sórí àwọn òkè, gbogbo ipadò yóo sì kún fún ẹ̀jẹ̀ rẹ̀.

7 Nígbà tí mo bá pa á rẹ́, n óo bo ojú ọ̀run; n óo jẹ́ kí ìràwọ̀ ṣóòkùn n óo fi ìkùukùu bo oòrùn lójú, òṣùpá kò sì ní tan ìmọ́lẹ̀.

8 Gbogbo àwọn ìmọ́lẹ̀ tí ó ń tàn lójú ọ̀run ni n óo jẹ́ kí ó di òkùnkùn lórí rẹ̀, n óo jẹ́ kí òkùnkùn bo ilẹ̀ rẹ̀. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

9 “N óo jẹ́ kí ọkàn ọpọlọpọ eniyan dààmú nígbà tí mo bá ko yín ní ìgbèkùn lọ sí ilẹ̀ tí ẹ kò dé rí, láàrin àwọn orílẹ̀-èdè ayé.

10 N óo jẹ́ kí ẹnu ya ọpọlọpọ eniyan nítorí yín, àwọn ọba àwọn orílẹ̀-èdè yóo sì wárìrì nítorí tiyín, nígbà tí mo bá ń fi idà mi lójú wọn, olukuluku wọn óo máa wárìrì nígbàkúùgbà nítorí ẹ̀mí ara rẹ̀, ní ọjọ́ ìṣubú rẹ.”

11 OLUWA Ọlọrun sọ fún ọba Ijipti pé, “Ọba Babiloni yóo fi idà pa yín.

12 N óo wá àwọn alágbára, àwọn tí wọ́n burú jùlọ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè, n óo jẹ́ kí gbogbo wọn fi idà pa ogunlọ́gọ̀ àwọn eniyan rẹ. Wọn yóo sọ ìgbéraga Ijipti di asán, ogunlọ́gọ̀ àwọn eniyan rẹ yóo sì parun.

13 N óo pa gbogbo ẹran ọ̀sìn Ijipti tí ó wà ní etí odò run. Àwọn eniyan kò sì ní fi ẹsẹ̀ da omi rú mọ́, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹranko kò ní fi pátákò da odò rú mọ́.

14 N óo wá jẹ́ kí odò wọn ó tòrò, kí wọn máa ṣàn bí òróró. Èmi OLUWA Ọlọrun, ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

15 Nígbà tí mo bá sọ ilẹ̀ Ijipti di ahoro, tí mo bá pa gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀ run; tí mo bá pa gbogbo àwọn tí ń gbé inú rẹ̀ run, wọn yóo mọ̀ nígbà náà pé èmi ni OLUWA.

16 Àwọn eniyan yóo máa kọ ọ̀rọ̀ yìí ní orin arò; àwọn ọmọbinrin ní àwọn orílẹ̀-èdè ni yóo máa kọ ọ́. Wọn óo máa kọ ọ́ nípa Ijipti ati ogunlọ́gọ̀ àwọn eniyan rẹ̀. Èmi, OLUWA Ọlọrun, ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

Orin Arò fún Àwọn Ará Ijipti

17 Ní ọjọ́ kẹẹdogun oṣù kinni, ọdún kejila tí a ti wà ní ìgbèkùn,

18 OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní, “Ìwọ ọmọ eniyan, sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn lórí ogunlọ́gọ̀ àwọn eniyan Ijipti, rán àwọn ati àwọn orílẹ̀-èdè ọlọ́lá yòókù lọ sinu isà òkú, sọ́dọ̀ àwọn tí wọ́n ti fi ilẹ̀ bora.

19 Sọ fún wọn pé,

‘Ta ni ó lẹ́wà jùlọ?

Sùn kalẹ̀, kí á sì tẹ́ ọ sọ́dọ̀ àwọn aláìkọlà.’

20 “Wọn yóo ṣubú láàrin àwọn tí wọ́n kú ikú ogun; ogunlọ́gọ̀ àwọn eniyan rẹ̀ yóo ṣubú pẹlu rẹ̀.

21 Àwọn olórí tí wọ́n jẹ́ akọni ati àwọn olùrànlọ́wọ́ wọn yóo máa sọ nípa wọn ninu isà òkú pé, ‘Àwọn aláìkọlà tí a fi idà pa ti ṣubú, wọ́n ti wọlẹ̀, wọ́n sùn, wọn kò lè mira.’

22 “Asiria náà wà níbẹ̀, pẹlu gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀. Ibojì àwọn tí wọ́n ti kú yí i ká. Gbogbo wọn ni wọ́n ti kú ikú ogun.

23 Ibojì rẹ̀ wà ní ìpẹ̀kun isà òkú. Ibojì àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sì tò yí tirẹ̀ ká. Àwọn tí ń dẹ́rù bani nígbà tí wọ́n wà láyé, gbogbo wọn ni wọ́n ti kú ikú ogun.

24 “Elamu náà wà níbẹ̀, pẹlu gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀, ibojì wọn yí ibojì rẹ̀ ká. Gbogbo wọn ni wọ́n ti kú ikú ogun. Wọ́n sì lọ sinu isà òkú ní àìkọlà abẹ́. Àwọn tí ń dẹ́rù bani nígbà tí wọ́n wà láàyè, wọ́n fi ìtìjú wọlẹ̀ lọ sí ìsàlẹ̀ ilẹ̀, wọn lọ bá àwọn tí wọ́n wà ní ipò òkú.

25 Wọ́n tẹ́ ibùsùn fún Elamu láàrin àwọn tí wọ́n kú sójú ogun pẹlu ogunlọ́gọ̀ àwọn eniyan rẹ̀. Ibojì wọn yí tirẹ̀ ká, gbogbo wọn ni a fi idà pa láìkọlà abẹ́. Wọ́n ń dẹ́rù ba àwọn eniyan nígbà tí wọ́n wà láàyè. Wọ́n fi ìtìjú wọlẹ̀ lọ, wọ́n lọ bá àwọn tí wọ́n wà ní ipò òkú. A kó gbogbo wọn pọ̀ mọ́ àwọn tí wọ́n kú sójú ogun.

26 “Meṣeki ati Tubali wà níbẹ̀ pẹlu ogunlọ́gọ̀ àwọn eniyan wọn. Ibojì wọn yí ibojì rẹ̀ ká, gbogbo wọn ni wọ́n kú lójú ogun ní aláìkọlà. Nítorí wọ́n ń dẹ́rù bani nígbà tí wọ́n wà láàyè.

27 Wọn kò sin wọ́n bí àwọn alágbára tí wọ́n wà ní àtijọ́ tí wọ́n sin sí ibojì pẹlu ohun ìjà ogun wọn lára wọn: àwọn tí a gbé orí wọn lé idà wọn, wọ́n sì fi asà wọn bo egungun wọn mọ́lẹ̀; nítorí àwọn alágbára wọnyi dẹ́rù bani nígbà tí wọ́n wà láàyè.

28 “Nítorí náà, a óo wó ọ mọ́lẹ̀, o óo sì sùn láàrin àwọn aláìkọlà pẹlu àwọn tí wọ́n kú lójú ogun.

29 “Edomu náà wà níbẹ̀ pẹlu àwọn ọba ati àwọn ìjòyè rẹ̀. Bí wọ́n ti lágbára tó, wọ́n sùn pẹlu àwọn tí wọ́n kú lójú ogun. Wọ́n sùn pẹlu àwọn aláìkọlà, pẹlu àwọn tí wọ́n ti lọ sí ipò òkú.

30 “Gbogbo àwọn olórí láti apá àríwá wà níbẹ̀, ati gbogbo àwọn ará Sidoni, tí wọ́n fi ìtìjú wọlé lọ sí ipò òkú pẹlu àwọn tí wọ́n kú lójú ogun. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n lo agbára wọn láti dẹ́rù bani, wọ́n sùn láìkọlà, pẹlu ìtìjú, pẹlu àwọn tí wọ́n kú lójú ogun. Pẹlu àwọn tí wọ́n lọ sinu isà òkú.

31 “Nígbà tí Farao bá rí wọn, Tòun ti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ tí a fi idà pa, yóo dá ara rẹ̀ lọ́kàn le, nítorí gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀.” OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.

32 “Mo mú kí Farao dẹ́rù ba àwọn eniyan nígbà tí ó wà láyé. Nítorí náà, a óo sin òun ati ogunlọ́gọ̀ àwọn eniyan rẹ̀ sí ààrin àwọn aláìkọlà, láàrin àwọn tí wọ́n kú lójú ogun.” Bẹ́ẹ̀ ni OLUWA Ọlọrun wí.

Categories
ISIKIẸLI

ISIKIẸLI 33

Ọlọrun Fi Isikiẹli Ṣe Aṣọ́de ní Israẹli

1 OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní,

2 “Ìwọ ọmọ eniyan, bá àwọn eniyan rẹ sọ̀rọ̀. Wí fún wọn pé bí mo bá jẹ́ kí ogun jà ní ilẹ̀ kan, tí àwọn eniyan ibẹ̀ bá yan ọ̀kan ninu wọn, tí wọ́n fi ṣe olùṣọ́;

3 bí ó bá rí ogun tí ń bọ̀ wá sí ilẹ̀ náà, tí ó bá fọn fèrè tí ó fi kìlọ̀ fún àwọn eniyan,

4 bí ẹnìkan bá gbọ́ ìró fèrè náà, ṣugbọn tí kò bá bìkítà fún ogun àgbọ́-tẹ́lẹ̀ yìí, bí ogun bá pa á orí ara rẹ̀ ni ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yóo wà.

5 Ó gbọ́ ìró fèrè ṣugbọn kò bìkítà, nítorí náà orí ara rẹ̀ ni ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yóo wà. Bí ó bá gbọ́ ìkìlọ̀ ni, kì bá gba ẹ̀mí ara rẹ̀ là.

6 Ṣugbọn bí olùṣọ́ bá rí i pé ogun ń bọ̀, tí kò bá fọn fèrè kí ó kìlọ̀ fún àwọn eniyan; bí ogun bá pa ẹnikẹ́ni ninu wọn, ẹni tí ogun pa yóo kú ninu ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ṣugbọn èmi OLUWA óo bèèrè ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ olùṣọ́ náà.

7 “Ọmọ eniyan, ìwọ ni mo yàn ní olùṣọ́ fún ilé Israẹli; nígbàkúùgbà tí o bá gbọ́ ọ̀rọ̀ kan lẹ́nu mi, o níláti bá mi kìlọ̀ fún wọn.

8 Bí mo bá wí fún eniyan burúkú pé yóo kú, tí o kò sì kìlọ̀ fún un pé kí ó yipada kúrò ní ọ̀nà ibi rẹ̀, eniyan burúkú náà yóo kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ṣugbọn ọwọ́ rẹ ni n óo ti bèèrè ẹ̀jẹ̀ rẹ̀.

9 Ṣugbọn bí ìwọ bá kìlọ̀ fún eniyan burúkú pé kí ó yipada kúrò ní ọ̀nà ibi rẹ̀, tí kò sì yipada, yóo kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ṣugbọn ìwọ ti gba ẹ̀mí ara tìrẹ là.

Ẹrù Ẹnìkọ̀ọ̀kan

10 “Ìwọ ọmọ eniyan, sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé mo gbọ́ ohun tí wọn ń sọ pé, ‘Àìdára wa ati ẹ̀ṣẹ̀ wa wà lórí wa, a sì ń joró nítorí wọn; báwo ni a óo ṣe yè?’

11 Wí fún wọn pé èmi OLUWA ní, mo fi ara mi búra pé inú mi kò dùn sí ikú eniyan burúkú, ohun tí mo fẹ́ ni pé kí ó yipada kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, kí ó sì yè. Ẹ yipada! Ẹ yipada kúrò ninu iṣẹ́ ibi yín, ẹ̀yin ọmọ Israẹli, kí ló dé tí ẹ fi fẹ́ kú?

12 “Ìwọ ọmọ eniyan, wí fún àwọn eniyan rẹ pé, bí olódodo bá dẹ́ṣẹ̀ ìwà òdodo rẹ̀ kò ní gbà á là, bẹ́ẹ̀ sì ni bí eniyan burúkú bá yí ìwà rẹ̀ pada, kò ní kú nítorí ìwà burúkú rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ sì ni bí olódodo bá dẹ́ṣẹ̀, kò ní yè nítorí òdodo rẹ̀.

13 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo wí fún olódodo pé yóo yè, bí ó bá gbójú lé òdodo ara rẹ̀, tí ó bá ń dẹ́ṣẹ̀, n kò ní ranti ọ̀kankan ninu ìwà òdodo rẹ̀, yóo kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó dá.

14 Bí mo bá sì wí fún eniyan burúkú pé dandan ni pé kí ó kú, bí ó bá yipada kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, tí ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ohun tí ó dára, tí ó sì tọ́,

15 bí ó bá dá nǹkan tí ẹni tí ó jẹ ẹ́ ní gbèsè fi ṣe ìdúró pada, tí ó sì dá gbogbo nǹkan tí ó jí pada, tí ó ń rìn ní ọ̀nà ìyè láì dẹ́ṣẹ̀, dájúdájú yóo yè; kò ní kú.

16 N kò ní ranti gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí o ti dá mọ́. Nítorí pé ó ti ṣe ohun tí ó dára, tí ó sì tọ́, yóo yè.

17 “Sibẹsibẹ, àwọn eniyan rẹ ń wí pé, ‘Ọ̀nà OLUWA kò tọ́,’ bẹ́ẹ̀ sì ni ọ̀nà tiwọn gan-an ni kò tọ́.

18 Bí olódodo bá yipada kúrò ninu ìwà òdodo rẹ̀, tí ó bá ń dẹ́ṣẹ̀, yóo kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.

19 Bí eniyan burúkú bá sì yipada kúrò ninu ibi tí ó ń ṣe, tí ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ohun tí ó dára tí ó sì tọ́, yóo yè nítorí rere tí ó ṣe.

20 Sibẹsibẹ, ẹ̀ ń wí pé, ‘ọ̀nà OLUWA kò tọ́.’ Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ìwà olukuluku yín ni n óo fi dá a lẹ́jọ́.”

Ìròyìn Nípa Ìṣubú Jerusalẹmu

21 Ní ọjọ́ karun-un oṣù kẹwaa ọdún kejila tí a ti wà ní ìgbèkùn, ẹnìkan tí ó sá àsálà kúrò ní Jerusalẹmu wá sọ́dọ̀ mi, ó ní, “Ogun ti kó Jerusalẹmu.”

22 Ẹ̀mí OLUWA ti bà lé mi ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ tí ó ṣáájú ọjọ́ tí ẹni tí ó sá àsálà náà dé, OLUWA sì ti là mí lóhùn kí ọkunrin náà tó dé ọ̀dọ̀ mi ní àárọ̀ ọjọ́ keji; n kò sì yadi mọ́.

Ẹ̀ṣẹ̀ Àwọn Eniyan náà

23 OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní:

24 “Ìwọ ọmọ eniyan, àwọn tí wọn ń gbé ilẹ̀ Israẹli tí ó ti di aṣálẹ̀ wọnyi, ń wí pé, ‘Ẹnìkan péré ni Abrahamu, bẹ́ẹ̀ ó sì gba ilẹ̀ yìí. Àwa pọ̀ ní tiwa, nítorí náà, a ti fi ilẹ̀ yìí fún wa, kí á gbà á ló kù.’

25 “Nítorí náà, wí fún wọn pé OLUWA Ọlọrun ní, Ẹ̀ ń jẹ ẹran pẹlu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ẹ̀ ń bọ oriṣa, ẹ sì ń pa eniyan, ṣé ẹ rò pé ilẹ̀ náà yóo di tiyín?

26 Idà ni ó kù tí ẹ gbẹ́kẹ̀lé; ẹ̀ ń ṣe ohun ìríra, ẹ̀ ń bá iyawo ara yín lòpọ̀, ẹ sì rò pé ẹ óo jogún ilẹ̀ yìí?

27 “Mo fi ara mi búra, ogun ni yóo pa àwọn tí ń gbé àwọn ìlú tí ó ti di ahoro. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀. N óo jẹ́ kí ẹranko burúkú pa àwọn tí wọ́n wà ninu pápá jẹ, àjàkálẹ̀ àrùn yóo sì pa àwọn tí wọ́n sápamọ́ sí ibi ààbò ati ninu ihò àpáta.

28 N óo sọ ilẹ̀ yìí di ahoro ati aṣálẹ̀. Agbára tí ó ń gbéraga sí yóo dópin. Àwọn òkè Israẹli yóo di ahoro tóbẹ́ẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò ní gba ibẹ̀ kọjá.

29 Wọn óo wá mọ̀ nígbà náà pé èmi ni OLUWA nígbà tí mo bá sọ ilẹ̀ náà di ahoro ati aṣálẹ̀, nítorí gbogbo ìwà ìríra tí wọ́n ti hù.

Àwọn Àbọ̀dé Ìran Wolii Náà

30 “Ní tìrẹ, ìwọ ọmọ eniyan, àwọn eniyan rẹ tí ń sọ̀rọ̀ rẹ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ògiri ati lẹ́nu ọ̀nà àbáwọlé wọn, wọ́n ń wí fún ara wọn pé: ‘Ẹ jẹ́ kí á lọ gbọ́ ohun tí OLUWA wí.’

31 Wọ́n ń wá sọ́dọ̀ rẹ bí àwọn eniyan tií wá, wọ́n sì ń jókòó níwájú rẹ bí eniyan mi. Wọ́n ń gbọ́ ohun tí ò ń wí, ṣugbọn wọn kò ní ṣe é; nítorí pé ẹnu lásán ni wọ́n fi ń sọ pé wọ́n ní ìfẹ́ pupọ, ṣugbọn níbi èrè tí wọn ó jẹ ni ọkàn wọn wà.

32 Lójú wọn, o dàbí olóhùn iyọ̀ tí ń kọrin ìfẹ́, tí ó sì mọ ohun èlò orin lò dáradára. Wọ́n ń gbọ́ ohun tí ò ń wí, ṣugbọn wọn kò ní ṣe é.

33 Ṣugbọn nígbà tí ọ̀rọ̀ rẹ bá ṣẹ, (bẹ́ẹ̀ yóo sì ṣẹ), wọn óo wá mọ̀ pé wolii kan wà láàrin wọn.”

Categories
ISIKIẸLI

ISIKIẸLI 34

Àwọn Olùṣọ́-Aguntan Israẹli

1 OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní,

2 “Ìwọ ọmọ eniyan, sọ àsọtẹ́lẹ̀ kí o fi bá àwọn olùṣọ́-aguntan Israẹli wí, fi àsọtẹ́lẹ̀ bá àwọn olórí Israẹli wí pé, OLUWA Ọlọrun ní, ‘Háà, ẹ̀yin olórí Israẹli tí ẹ̀ ń wá oúnjẹ fún ara yín, ṣé kò yẹ kí olùṣọ́-aguntan máa pèsè oúnjẹ fún àwọn aguntan rẹ̀?

3 Ẹ̀yin ń jẹ ẹran ọlọ́ràá, ẹ̀ ń fi irun aguntan bo ara yín, ẹ̀ ń pa aguntan tí ó sanra jẹ; ṣugbọn ẹ kò fún àwọn aguntan ní oúnjẹ.

4 Ẹ kò tọ́jú àwọn tí wọn kò lágbára, ẹ kò tọ́jú àwọn tí ń ṣàìsàn, ẹ kò tọ́jú ẹsẹ̀ àwọn tí wọn dá lẹ́sẹ̀, ẹ kò mú àwọn tí wọn ń ṣáko lọ pada wálé; ẹ kò sì wá àwọn tí wọ́n sọnù. Pẹlu ipá ati ọwọ́-líle ni ẹ fi ń ṣe àkóso wọn.

5 Nítorí náà, wọ́n túká nítorí pé wọn kò ní olùṣọ́, wọ́n sì di ìjẹ fún àwọn ẹranko burúkú.

6 Àwọn aguntan mi túká, wọ́n ń káàkiri lórí gbogbo òkè ńlá ati gbogbo òkè kéékèèké. Àwọn aguntan mi fọ́n káàkiri sórí gbogbo ilẹ̀ ayé. Kò sí ẹni tí ó bèèrè wọn, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹni tí ó wá wọn.’

7 “Nítorí náà, ẹ̀yin, olùṣọ́-aguntan, ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA wí.

8 OLUWA Ọlọrun fi ara rẹ̀ búra ó ní, ‘Àwọn aguntan mi di ìjẹ, fún gbogbo ẹranko nítorí pé wọn kò ní olùṣọ́; nítorí pé àwọn tí ń ṣọ́ wọn kò wá wọn, kàkà bẹ́ẹ̀ oúnjẹ ni wọ́n ń wá sẹ́nu ara wọn, wọn kò bọ́ àwọn aguntan mi.’

9 Nítorí náà, ẹ gbọ́, ẹ̀yin olùṣọ́-aguntan:

10 ‘Mo lòdì sí ẹ̀yin olùṣọ́-aguntan, n óo sì bèèrè àwọn aguntan mi lọ́wọ́ yín. N óo da yín dúró lẹ́nu iṣẹ́ olùṣọ́-aguntan, ẹ kò sì ní rí ààyè bọ́ ara yín mọ́. N óo gba àwọn aguntan mi lẹ́nu yín, ẹ kò sì ní rí wọn pa jẹ mọ́.’ ”

Olùṣọ́-Aguntan Rere Náà

11 OLUWA Ọlọrun ní, “Ẹ wò ó! Èmi fúnra mi ni n óo wá àwọn aguntan mi, àwárí ni n óo sì wá wọn.

12 Bí olùṣọ́-aguntan tií wá àwọn aguntan rẹ̀ tí ó bá jẹ lọ, bẹ́ẹ̀ ni n óo wá àwọn aguntan mi, n óo sì yọ wọ́n kúrò ninu gbogbo ibi tí wọ́n fọ́nká sí ní ọjọ́ tí ìkùukùu bo ilẹ̀, tí òkùnkùn sì ṣú.

13 N óo mú wọn jáde kúrò láàrin àwọn orílẹ̀-èdè yòókù, n óo kó wọn jọ láti gbogbo ilẹ̀ ayé, n óo sì kó wọn wá sí ilẹ̀ tiwọn. N óo máa bọ́ wọn lórí àwọn òkè Israẹli, lẹ́bàá orísun omi ati gbogbo ibi tí àwọn eniyan ń gbé ní Israẹli.

14 N óo fún wọn ní koríko tí ó dára jẹ, orí òkè Israẹli sì ni wọn óo ti máa jẹ koríko. Níbẹ̀, ninu pápá oko tí ó dára ni wọn óo dùbúlẹ̀ sí; ninu pápá oko tútù, wọn yóo sì máa jẹ lórí àwọn òkè Israẹli.

15 Èmi fúnra mi ni n óo jẹ́ olùṣọ́ àwọn aguntan mi, n óo sì mú wọn dùbúlẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni èmi OLUWA Ọlọrun sọ.

16 “N óo wá àwọn tí ó sọnù, n óo sì mú àwọn tí wọ́n ṣáko lọ pada, n óo tọ́jú ọgbẹ́ àwọn tí wọ́n farapa, n óo fún àwọn tí kò lókun lágbára, ṣugbọn àwọn tí wọ́n sanra ati àwọn tí wọ́n lágbára ni n óo parun, nítorí òtítọ́ inú ni n óo fi ṣọ́ àwọn aguntan mi.

17 “Ní tiyín, ẹ̀yin agbo ẹran mi, èmi OLUWA Ọlọrun ni n óo ṣe ìdájọ́ láàrin aguntan kan ati aguntan keji, ati láàrin àgbò ati òbúkọ.

18 Ṣé kí ẹ máa jẹ oko ninu pápá dáradára kò to yín ni ẹ ṣe ń fi ẹsẹ̀ tẹ àjẹkù yín mọ́lẹ̀? Ṣé kí ẹ mu ninu omi tí ó tòrò kò to yín ni ẹ ṣe fẹsẹ̀ da omi yòókù rú?

19 Ṣé àjẹkù tí ẹ ti fi ẹsẹ̀ tẹ̀ mọ́lẹ̀ ni ó yẹ kí àwọn aguntan tèmi máa jẹ; omi àmukù tí ẹ ti fi ẹsẹ̀ dàrú sì ni ó yẹ kí wọn máa mu?

20 “Nítorí náà, ohun tí èmi OLUWA Ọlọrun, ń sọ fun yín ni pé: mo ṣetán tí n óo ṣe ìdájọ́ fún àwọn aguntan tí ó sanra ati àwọn aguntan tí kò lókun ninu.

21 Nítorí pé ẹ̀ ń fi ẹ̀gbẹ́ ti àwọn tí wọn kò lágbára sọnù, ẹ sì ń kàn wọ́n níwo títí tí ẹ fi tú wọn ká.

22 N óo gba àwọn aguntan mi sílẹ̀, wọn kò ní jẹ́ ìjẹ mọ́, n óo sì ṣe ìdájọ́ láàrin aguntan kan ati aguntan keji.

23 Olùṣọ́ kanṣoṣo ni n óo yàn fún wọn, òun náà sì ni Dafidi, iranṣẹ mi. Yóo máa bọ́ wọn, yóo sì máa ṣe olùṣọ́ wọn.

24 Èmi OLUWA ni n óo jẹ́ Ọlọrun wọn; Dafidi, iranṣẹ mi ni yóo sì jẹ́ ọba láàrin wọn, èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

25 N óo bá wọn dá majẹmu alaafia; n óo lé àwọn ẹranko burúkú kúrò ní ilẹ̀ náà, wọn yóo máa gbé inú aṣálẹ̀ ati inú igbó láìléwu.

26 “N óo bukun àwọn, ati gbogbo agbègbè òkè mi. N óo máa jẹ́ kí òjò máa rọ̀ lásìkò wọn, òjò ibukun ni yóo sì máa jẹ́.

27 Igi inú oko yóo máa so; ilẹ̀ yóo sì máa mú ọpọlọpọ irúgbìn jáde. Àwọn eniyan óo máa gbé ilẹ̀ wọn láìléwu, wọn óo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA nígbà tí mo bá ṣẹ́ ọ̀pá àjàgà wọn, tí mo bá sì gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn tí ó kó wọn lẹ́rú.

28 Wọn kò ní jẹ́ ìjẹ fún àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn mọ́; bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹranko ilẹ̀ yìí kò ní pa wọ́n jẹ mọ́. Wọn óo máa gbé ilẹ̀ wọn láìléwu, ẹnìkan kan kò sì ní dẹ́rù bà wọ́n mọ́.

29 N óo fún wọn ní ọpọlọpọ nǹkan kórè ninu ohun tí wọ́n bá gbìn, ìyàn kò ní run wọ́n mọ́ ní ilẹ̀ náà, àwọn orílẹ̀-èdè yòókù kò sì ní fi wọ́n ṣẹ̀sín mọ́.

30 Wọn óo mọ̀ pé èmi, OLUWA Ọlọrun wọn, wà pẹlu wọn, ati pé àwọn ọmọ Israẹli sì ni eniyan mi. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

31 “Ẹ̀yin aguntan mi, aguntan pápá mi, ẹ̀yin ni eniyan mi; èmi sì ni Ọlọrun yín.” OLUWA Ọlọrun ló sọ bẹ́ẹ̀.

Categories
ISIKIẸLI

ISIKIẸLI 35

Ìyà Tí Ọlọrun óo Fi Jẹ Edomu

1 OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní,

2 “Ìwọ ọmọ eniyan, dojú kọ òkè Seiri, kí o sì fi àsọtẹ́lẹ̀ bá a wí.

3 Wí fún un pé OLUWA Ọlọrun ní,

‘Wò ó! Mo lòdì sí ọ,

ìwọ Òkè Seiri.

N óo nawọ́ ibinu sí ọ,

n óo sọ ọ́ di ahoro ati aṣálẹ̀.

4 N óo sọ àwọn ìlú rẹ di aṣálẹ̀

ìwọ pàápàá yóo sì di ahoro;

o óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA.

5 “ ‘Nítorí pé ò ń fẹ́ràn ati máa ṣe ọ̀tá lọ títí, o sì fa àwọn ọmọ Israẹli fún ogun pa nígbà tí ìṣòro dé bá wọn, tí wọn ń jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

6 Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun ní, mo fi ara mi búra pé, n óo fi ọ́ fún ikú pa, ikú yóo máa lépa rẹ, nítorí pé apànìyàn ni ọ́; ikú yóo máa lépa ìwọ náà.

7 N óo sọ òkè Seiri di aṣálẹ̀ ati ahoro. N óo pa gbogbo àwọn tí ń lọ tí ń bọ̀ níbẹ̀.

8 N óo da òkú sí orí àwọn òkè ńláńlá rẹ, yóo kún. Bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn òkè kéékèèké rẹ, ati gbogbo àwọn àfonífojì rẹ, ati gbogbo ipa odò rẹ. Òkú àwọn tí a fi idà pa ni yóo kúnbẹ̀.

9 N óo sọ ọ́ di ahoro títí lae, ẹnikẹ́ni kò sì ní gbé inú àwọn ìlú rẹ mọ́. O óo wá mọ̀ nígbà náà pé èmi ni OLUWA.

10 “ ‘Nítorí ẹ̀yin ará Edomu sọ pé, àwọn orílẹ̀-èdè mejeeji wọnyi ati ilẹ̀ wọn yóo di tiyín ati pé ẹ óo jogún rẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé OLUWA wà níbẹ̀.

11 Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun ní, mo fi ara mi búra, bí ẹ ti fi ìrúnú ati owú ṣe sí wọn nítorí pé ẹ kórìíra wọn, bẹ́ẹ̀ gan-an ni èmi náà óo ṣe sí ọ; n óo sì jẹ́ kí ẹ mọ irú ẹni tí mo jẹ́ nígbà tí mo bá dájọ́ fun yín.

12 Ẹ óo mọ̀ pé èmi OLUWA gbọ́ gbogbo ohun tí ẹ̀ ń sọ sí àwọn òkè Israẹli, pé wọ́n ti di ahoro ati ìkógun fun yín.

13 Ẹ̀ ń fi ẹnu yín sọ̀rọ̀ ìgbéraga sí mi, ẹ sì ń dá àpárá lù mí; gbogbo rẹ̀ ni mo gbọ́.’ ”

14 OLUWA Ọlọrun ní, “N óo sọ ìwọ Edomu di ahoro, kí gbogbo ayé lè yọ̀ ọ́;

15 bí o ti yọ ilẹ̀ Israẹli nígbà tí ilé wọn di ahoro. Bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe sí ọ, ìwọ náà óo di ahoro. Gbogbo òkè Seiri ati gbogbo ilẹ̀ Edomu yóo di ahoro. Ẹ óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA.”

Categories
ISIKIẸLI

ISIKIẸLI 36

Ibukun Ọlọrun Lórí Israẹli

1 OLUWA ní, “Ìwọ ọmọ eniyan, fi àsọtẹ́lẹ̀ bá àwọn òkè Israẹli wí. Sọ pé, ‘Ẹ̀yin òkè Israẹli, ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA wí:

2 Àwọn ọ̀tá ń yọ̀ yín, wọ́n ń sọ pé, àwọn òkè àtijọ́ ti di ogún àwọn.’

3 “Nítorí náà, ó ní kí n sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé òun OLUWA Ọlọrun ní nítorí pé wọ́n ti sọ ẹ̀yin òkè Israẹli di ahoro, wọ́n sì ja yín gbà lọ́tùn-ún lósì, títí tí ẹ fi di ìkógun fún àwọn orílẹ̀-èdè yòókù, àwọn eniyan sì ń sọ ọ̀rọ̀ yín ní ìsọkúsọ,

4 nítorí náà, ẹ gbọ́ ohun tí èmi OLUWA wí, kí ẹ̀yin òkè ńláńlá ati ẹ̀yin òkè kéékèèké Israẹli, ẹ̀yin ipa odò ati ẹ̀yin àfonífojì, ẹ̀yin ibi tí ẹ ti di aṣálẹ̀ ati ẹ̀yin ìlú tí ẹ ti di ahoro, ẹ̀yin ìlú tí ẹ di ìjẹ ati yẹ̀yẹ́ fún àwọn orílẹ̀-èdè yòókù tí wọ́n yi yín ká.

5 “N óo fi ìtara sọ̀rọ̀ sí àwọn orílẹ̀-èdè yòókù ati gbogbo Edomu, tí wọ́n fi tayọ̀tayọ̀ pẹlu ọkàn ìkórìíra sọ ilẹ̀ mi di ogún wọn, kí wọ́n lè gbà á, kí wọ́n sì pín in mọ́wọ́, nítorí wọ́n rò pé ilẹ̀ mi ti di tiwọn.

6 “Nítorí náà, sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ilẹ̀ Israẹli. Wí fún àwọn òkè ńláńlá ati àwọn òkè kéékèèké, ati àwọn ipa odò ati àwọn àfonífojì, pé èmi OLUWA Ọlọrun ní ìtara ati ìgbónára ni mo fi ń sọ̀rọ̀ nítorí pé ẹ ti jìyà pupọ, ẹ sì ti di ẹni ẹ̀gàn lọ́wọ́ àwọn orílẹ̀-èdè yòókù.

7 Nítorí náà, èmi OLUWA Ọlọrun, ń ṣe ìbúra pé, àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n wà ní àyíká yín yóo di ẹni ẹ̀sín.

8 Ṣugbọn ẹ̀yin òkè Israẹli, igi óo hù lórí yín, wọn óo sì so èso fún Israẹli, àwọn eniyan mi, nítorí pé wọn kò ní pẹ́ pada wálé.

9 Nítorí pé mo wà fun yín, n óo ṣí ojú àánú wò yín, wọn óo dá oko sórí yín, wọn óo sì gbin nǹkan sinu rẹ̀.

10 N óo sọ àwọn ọmọ Israẹli tí ń gbé orí yín di pupọ. Àwọn ìlú yóo rí ẹni máa gbé inú wọn, wọn óo sì tún gbogbo ibi tí ó ti wó kọ́.

11 N óo sọ eniyan ati ẹran ọ̀sìn di pupọ lórí yín, wọn óo máa bímọlémọ, wọn ó sì di ọ̀kẹ́ àìmọye. N óo mú kí eniyan máa gbé orí yín bí ìgbà àtijọ́, nǹkan ó sì dára fun yín ju ti àtẹ̀yìnwá lọ. Ẹ óo wá mọ̀ nígbà náà pé èmi ni OLUWA.

12 N óo jẹ́ kí àwọn eniyan mi, àní àwọn ọmọ Israẹli, máa rìn bọ̀ lórí yín. Àwọn ni wọn óo ni yín, ẹ óo sì di ogún wọn, ẹ kò ní pa wọ́n lọ́mọ mọ́.

13 “Nítorí àwọn eniyan ń wí pé ò ń paniyan, ati pé ò ń run àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè rẹ.

14 Nítorí náà, o kò ní pa eniyan mọ́, o kò sì ní pa àwọn eniyan rẹ lọ́mọ mọ́, Èmi OLUWA Ọlọrun ni ó sọ bẹ́ẹ̀.

15 N kò ní jẹ́ kí o gbọ́ ẹ̀gàn àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn mọ́, bẹ́ẹ̀ ni àwọn eniyan kò ní dójútì ọ́ mọ́, n kò sì ní mú kí orílẹ̀-èdè rẹ kọsẹ̀ mọ́. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

Ìgbé-Ayé Titun Israẹli

16 OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní,

17 “Ìwọ ọmọ eniyan, nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli ń gbé ilẹ̀ wọn, wọ́n fi ìwà burúkú ba ilẹ̀ náà jẹ́. Lójú mi, ìwà wọn dàbí ìríra obinrin tí ń ṣe nǹkan oṣù rẹ̀ lọ́wọ́.

18 Mo bá bínú sí wọn gan-an nítorí ẹ̀jẹ̀ tí wọ́n ta sílẹ̀ ní ilẹ̀ náà ati oriṣa tí wọ́n fi bà á jẹ́.

19 Mo fọ́n wọn ká sáàrin àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, wọ́n sì tú káàkiri orí ilẹ̀ ayé. Ìwà ati ìṣe wọn ni mo fi dá wọn lẹ́jọ́.

20 Nígbà tí wọ́n dé orílẹ̀-èdè tí mo fọ́n wọn ká sí, wọ́n bà mí lórúkọ jẹ́, nítorí àwọn eniyan ń sọ nípa wọn pé, ‘Eniyan OLUWA ni àwọn wọnyi, sibẹsibẹ wọ́n kúrò lórí ilẹ̀ OLUWA.’

21 Ṣugbọn mo ní ìtara fún orúkọ mímọ́ mi, tí àwọn ọmọ Israẹli sọ di nǹkan yẹ̀yẹ́ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n wà.

22 “Nítorí náà, OLUWA ní kí n pe ẹ̀yin, ọmọ Israẹli, kí n sọ fun yín pé, òun OLUWA Ọlọrun ní, Kì í ṣe nítorí tiyín ni mo fi ń ṣe ohun tí mò ń ṣe, bíkòṣe nítorí orúkọ mímọ́ mi, tí ẹ̀ ń bàjẹ́ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tí ẹ sálọ.

23 N óo fihàn bí orúkọ ńlá mi, tí ó ti bàjẹ́ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè ti jẹ́ mímọ́ tó, àní orúkọ mi tí ẹ bàjẹ́ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tí ẹ wà. Wọn yóo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA Ọlọrun, nígbà tí mo bá ti ipasẹ̀ yín fi bí orúkọ mi ti jẹ́ mímọ́ tó hàn wọ́n.

24 Nítorí pé n óo ko yín jáde láti inú àwọn orílẹ̀-èdè yòókù, n óo gba yín jọ láti gbogbo ilẹ̀ ayé, n óo sì mu yín pada sórí ilẹ̀ yín.

25 N óo wọ́n omi mímọ́ si yín lórí, àìmọ́ yín yóo sì di mímọ́. N óo wẹ̀ yín mọ́ kúrò ninu gbogbo ìbọ̀rìṣà yín.

26 N óo fun yín ní ọkàn titun, n óo sì fi ẹ̀mí titun si yín ninu. N óo yọ ọkàn tí ó le bí òkúta kúrò, n óo sì fun yín ní ọkàn tí ó rọ̀ bí ẹran ara.

27 N óo fi ẹ̀mí mi si yín ninu, n óo mú kí ẹ máa rìn ní ìlànà mi, kí ẹ sì máa fi tọkàntọkàn pa òfin mi mọ́.

28 Ẹ óo sì máa gbé orí ilẹ̀ tí mo fún àwọn baba ńlá yín. Ẹ óo jẹ́ eniyan mi, n óo sì máa jẹ́ Ọlọrun yín.

29 N óo gbà yín kúrò ninu gbogbo ìwà èérí yín. N óo mú ọkà pọ̀ ní ilé yín, n kò sì ní jẹ́ kí ìyàn mu yín mọ́.

30 N óo jẹ́ kí èso igi ati èrè oko pọ̀, tóbẹ́ẹ̀ tí ìtìjú kò ní ba yín láàrin àwọn orílẹ̀-èdè mọ́ nítorí ìyàn.

31 Nígbà náà ni ẹ óo ranti ìrìnkurìn ati ìwà burúkú yín, ara yín óo sì su yín nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yín ati ìwà ìríra yín.

32 Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájú pé kì í ṣe nítorí yín ni n óo fi ṣe bẹ́ẹ̀. Ẹ jẹ́ kí ojú tì yín, kí ẹ sì dààmú nítorí ìwà yín, ẹ̀yin ọmọ Israẹli. Èmi OLUWA Ọlọrun, ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

33 OLUWA Ọlọrun ní, “Ní ọjọ́ tí mo bá wẹ̀ yín mọ́ kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀ yín, n óo jẹ́ kí àwọn eniyan máa gbé inú àwọn ìlú yín, n óo sì mú kí wọ́n tún àwọn ibi tí ó wó lulẹ̀ kọ́.

34 A óo dá oko sórí àwọn ilẹ̀ tí wọ́n ti di igbó, dípò kí ó máa wà ní igbó lójú àwọn tí wọn ń kọjá lọ.

35 Wọn yóo wí pé, ‘Ilẹ̀ yìí, tí ó ti jẹ́ igbó nígbà kan rí, ti dàbí ọgbà Edẹni, àwọn eniyan sì ti ń gbé àwọn ìlú tí wọ́n ti wó lulẹ̀, tí wọ́n ti di ahoro, tí wọ́n sì ti run tẹ́lẹ̀; a sì ti mọ odi wọn pada.’

36 Àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n wà ní àyíká yín yóo wá mọ̀ nígbà náà pé èmi OLUWA ni mo tún àwọn ibùgbé yín tí ó wó lulẹ̀ kọ́, tí mo sì tún gbin nǹkan ọ̀gbìn sí ilẹ̀ yín tí ó di igbó. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni n óo sì ṣe.”

37 OLUWA Ọlọrun ní, “Ohun kan tí n óo tún mú kí àwọn ọmọ Israẹli bèèrè lọ́wọ́ mi pé kí n ṣe fún àwọn ni pé kí n máa mú kí àwọn ọmọ wọn pọ̀ sí i bí ọ̀wọ́ aguntan.

38 Kí wọn pọ̀ bí ọ̀wọ́ ẹran, àní bí ọ̀wọ́ ẹran ìrúbọ tíí pọ̀ ní Jerusalẹmu ní àkókò àjọ̀dún. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ìlú tí a ti wó palẹ̀ yóo kún fún ọ̀pọ̀ eniyan. Wọn óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA.”

Categories
ISIKIẸLI

ISIKIẸLI 37

Àfonífojì Tí ó kún fún Egungun Gbígbẹ

1 Agbára OLUWA sọ̀kalẹ̀ sára mi, ẹ̀mí rẹ̀ sì gbé mi wá sinu àfonífojì tí ó kún fún egungun.

2 Ó mú mi la ààrin wọn kọjá; àwọn egungun náà pọ̀ gan-an ninu àfonífojì náà; wọ́n sì ti gbẹ.

3 OLUWA bá bi mí léèrè, ó ní, “Ìwọ ọmọ eniyan, ǹjẹ́ àwọn egungun wọnyi lè tún jí?”

Mo bá dáhùn, mo ní, “OLUWA, ìwọ nìkan ni o mọ̀.”

4 Ó bá sọ fún mi pé, “Sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún àwọn egungun wọnyi, kí o wí fún wọn pé, ‘Ẹ̀yin egungun gbígbẹ wọnyi, ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA wí’.

5 Ó ní: ‘N óo mú kí èémí wọ inú yín, ẹ óo sì di alààyè.

6 N óo fi iṣan bò yín lára; lẹ́yìn náà n óo fi ara ẹran bò yín, n óo sì da awọ bò yín lára. N óo wá fi èémí si yín ninu, ẹ óo di alààyè, ẹ óo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA.’ ”

7 Mo bá sọ àsọtẹ́lẹ̀ bí OLUWA ti pàṣẹ fún mi. Bí mo ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ tán, mo bẹ̀rẹ̀ sí gbọ́ ariwo ati ìrọ́kẹ̀kẹ̀, àwọn egungun náà sì bẹ̀rẹ̀ sí so mọ́ ara wọn; egungun ń so mọ́ egungun.

8 Kí n tó ṣẹ́jú pẹ́, iṣan ti dé ara wọn, ẹran ti bo iṣan, awọ ara sì ti bò wọ́n, ṣugbọn kò tíì sí èémí ninu wọn.

9 OLUWA bá sọ fún mi pé, “Ìwọ ọmọ eniyan, sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún èémí, sọ fún un pé OLUWA Ọlọrun ní: ‘Wá, ìwọ èémí láti orígun mẹrẹẹrin ilẹ̀ ayé, kí o fẹ́ sinu àwọn òkú wọnyi, kí wọ́n di alààyè.’ ”

10 Mo bá sọ àsọtẹ́lẹ̀ bí ó ti pàṣẹ fún mi. Èémí wọ inú wọn, wọ́n sì di alààyè; ogunlọ́gọ̀ eniyan ni wọ́n, wọ́n bá dìde dúró!

11 OLUWA bá sọ fún mi pé, “Ìwọ ọmọ eniyan, àwọn ọmọ Israẹli ni àwọn egungun wọnyi. Wọ́n ń sọ pé, ‘Egungun wa ti gbẹ; kò sí ìrètí fún wa mọ́, a ti pa wá run patapata.’

12 Nítorí náà, sọ àsọtẹ́lẹ̀ kí o wí fún wọn pé OLUWA Ọlọrun ní, ‘N óo ṣí ibojì yín; n óo sì gbe yín dìde, ẹ̀yin eniyan mi, n óo mu yín pada sí ilé, ní ilẹ̀ Israẹli.

13 Ẹ̀yin eniyan mi, nígbà tí mo bá ṣí ibojì yín, tí mo sì gbe yín dìde, ẹ óo mọ̀ pé èmi ni OLUWA.

14 N óo fi ẹ̀mí mi sinu yín, ẹ óo sì tún wà láàyè; n óo sì mu yín wá sí ilẹ̀ yín. Ẹ óo wá mọ̀ pé èmi OLUWA ni mo wí bẹ́ẹ̀, tí mo sì ṣe bẹ́ẹ̀.’ ”

Juda ati Israẹli Yóo Di Orílẹ̀-Èdè Kan

15 OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní,

16 “Ìwọ ọmọ eniyan, mú igi kan kí o kọ sí ara rẹ̀ pé, ‘Igi Juda ati àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀.’ Mú igi mìíràn kí o kọ sí ara rẹ̀ pé, ‘Ti Josẹfu, (igi Efuraimu) ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀.’

17 Fi ẹnu wọn ko ara wọn, kí wọ́n di igi kan lọ́wọ́ rẹ.

18 Bí àwọn eniyan rẹ bá bi ọ́ pé kí ni ìtumọ̀ ohun tí ò ń ṣe yìí?

19 Wí fún wọn pé èmi OLUWA Ọlọrun ní: ‘N óo mú igi Josẹfu ati àwọn ìdílé Israẹli tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀, n óo fi ẹnu rẹ̀ ko ẹnu igi Juda; n óo sọ wọ́n di igi kan, wọn yóo sì di ọ̀kan lọ́wọ́ mi.’

20 “Mú àwọn igi tí o kọ nǹkan sí lára lọ́wọ́, lójú wọn,

21 kí o sọ fún wọn pé OLUWA Ọlọrun ní, ‘Ẹ wò ó! N óo kó àwọn ọmọ Israẹli jọ láti gbogbo orílẹ̀-èdè tí wọ́n wà, n óo kó wọn jọ láti ibi gbogbo wá sí ilẹ̀ wọn.

22 N óo sọ wọ́n di orílẹ̀-èdè kan ní orí òkè Israẹli, ọba kanṣoṣo ni yóo sì jẹ lé gbogbo wọn lórí. Wọn kò ní jẹ́ orílẹ̀-èdè meji mọ́; wọn kò ní pín ara wọn sí ìjọba meji mọ́.

23 Wọn kò ní fi ìbọ̀rìṣà kankan, tabi ìwà ìríra kankan tabi ẹ̀ṣẹ̀ wọn, sọ ara wọn di aláìmọ́ mọ́. N óo gbà wọ́n ninu gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ ìfàsẹ́yìn tí wọ́n ti dá. N óo wẹ̀ wọ́n mọ́, wọn yóo máa jẹ́ eniyan mi, èmi náà óo sì jẹ́ Ọlọrun wọn.

24 Dafidi, iranṣẹ mi ni yóo jọba lórí wọn; gbogbo wọn óo ní olùṣọ́ kan. Wọn óo máa pa òfin mi mọ́, wọn óo sì máa fi tọkàntọkàn rìn ní ìlànà mi.

25 Wọn óo máa gbé ilẹ̀ tí mo fún Jakọbu iranṣẹ mi, ilẹ̀ tí àwọn baba ńlá yín gbé. Àwọn ati àwọn ọmọ wọn ati àwọn ọmọ ọmọ wọn yóo máa gbé ibẹ̀ títí lae. Dafidi iranṣẹ mi ni yóo sì jẹ́ ọba wọn títí lae.

26 N óo bá wọn dá majẹmu alaafia, tí yóo jẹ́ majẹmu ayérayé. N óo bukun wọn, n óo jẹ́ kí wọn pọ̀ sí i, n óo sì gbé ilé mímọ́ mi kalẹ̀ sí ààrin wọn títí lae.

27 N óo kọ́ ibùgbé mi sí ààrin wọn, n óo jẹ́ Ọlọrun wọn, wọn yóo sì jẹ́ eniyan mi.

28 Àwọn orílẹ̀-èdè yòókù yóo wá mọ̀ pé èmi OLUWA ni mo ya Israẹli sọ́tọ̀, nígbà tí ibi mímọ́ mi bá wà láàrin wọn títí lae.’ ”

Categories
ISIKIẸLI

ISIKIẸLI 38

Gogu Gẹ́gẹ́ Bí Ohun Èlò Ọlọrun

1 OLUWA bá mi sọ̀rọ̀,

2 ó ní: “Ìwọ ọmọ eniyan, kọjú sí Gogu, ní ilẹ̀ Magogu; tí ó jẹ́ olórí Meṣeki ati Tubali,

3 kí o sì fi àsọtẹ́lẹ̀ bá a wí, pé OLUWA Ọlọrun ní, Mo lòdì sí ọ, ìwọ Gogu, olórí Meṣeki ati Tubali.

4 N óo yí ojú rẹ pada, n óo fi ìwọ̀ kọ́ ọ lẹ́nu, n óo sì mú ọ jáde, pẹlu gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ, ati àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ, ati àwọn ati ẹṣin wọn, gbogbo wọn, tàwọn ti ihamọra wọn, ogunlọ́gọ̀ àwọn ọmọ ogun tí wọ́n ní asà ati apata, tí wọ́n sì ń fi idà wọn.

5 Àwọn ará Pasia, ati àwọn ará Kuṣi, ati àwọn ará Puti wà pẹlu rẹ̀; gbogbo wọn, tàwọn ti apata ati àṣíborí wọn.

6 Gomeri ati gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀, ati Beti Togama láti òpin ilẹ̀ ìhà àríwá ati gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀; bẹ́ẹ̀ náà ni ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè, wọ́n wà pẹlu rẹ̀.

7 Dira ogun, kí o sì wà ní ìmúrasílẹ̀, ìwọ ati gbogbo eniyan tí wọ́n pé yí ọ ká, kí o jẹ́ olórí ẹ̀ṣọ́ fún wọn.

8 Lẹ́yìn ọpọlọpọ ọjọ́ a óo ko yín jọ. Ní ọdún mélòó kan sí i, ẹ óo gbógun ti ilẹ̀ tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bọ̀ sípò lẹ́yìn ìparun ogun, orílẹ̀-èdè tí a ṣà jọ láti ààrin ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè mìíràn sórí àwọn òkè ńláńlá Israẹli, ilẹ̀ tí ó ti wà ní ahoro fún ọpọlọpọ ọdún. Láti inú àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn ni a ti ṣa àwọn eniyan rẹ̀ jọ; nisinsinyii, gbogbo wọn wà láìléwu.

9 Ẹ óo gbéra, ẹ óo máa bọ̀ bí ìjì líle, ẹ óo dàbí ìkùukùu tí ó bo ilẹ̀, ìwọ ati gbogbo ọmọ ogun rẹ, pẹlu ọpọlọpọ eniyan tí ó wà pẹlu rẹ.”

10 OLUWA Ọlọrun ní, “Ní ọjọ́ náà èròkerò yóo wá sí ọkàn rẹ,

11 o óo wí ninu ara rẹ pé, ‘N óo gbógun ti ilẹ̀ tí kò ní odi yìí; n óo kọlu àwọn tí wọ́n jókòó jẹ́ẹ́jẹ́ wọn láìléwu, gbogbo wọn ń gbé ìlú tí kò ní odi, kò sì ní ìlẹ̀kùn, kí á má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ ti ọ̀pá ìdábùú ìlẹ̀kùn.’

12 N óo lọ kó wọn lẹ́rù, n óo sì kó ìkógun. N óo kọlu àwọn ilẹ̀ tí ó ti di ahoro nígbà kan rí, ṣugbọn tí àwọn eniyan ń gbé ibẹ̀ nisinsinyii, àwọn eniyan tí a ṣà jọ láti ààrin àwọn orílẹ̀-èdè, ṣugbọn tí wọ́n ní mààlúù ati ohun ìní, tí wọ́n sì ń gbé ìkóríta ilẹ̀ ayé.

13 Ṣeba ati Dedani ati àwọn oníṣòwò Taṣiṣi, ati àwọn ìlú agbègbè wọn yóo bi ọ́ pé, ‘Ṣé o wá kó ìkógun ni, ṣé o kó àwọn ọmọ ogun rẹ jọ láti wá kó ẹrú, fadaka ati wúrà, ati mààlúù, ọrọ̀ ati ọpọlọpọ ìkógun?’ ”

14 Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun ní kí n fi àsọtẹ́lẹ̀ bá Gogu wí pé, OLUWA Ọlọrun ní: “Ní ọjọ́ tí àwọn eniyan mi, àwọn ọmọ Israẹli, bá ń gbé láìléwu, ìwọ óo gbéra ní ààyè rẹ

15 ní ọ̀nà jíjìn, ní ìhà àríwá, ìwọ ati ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè, gbogbo wọn lórí ẹṣin, ọpọlọpọ eniyan, àní, àwọn ọmọ ogun.

16 O óo kọlu àwọn ọmọ Israẹli, àwọn eniyan mi, bí ìkùukùu tí ń ṣú bo ilẹ̀. Nígbà tí ó bá yà n óo mú kí o kọlu ilẹ̀ mi, kí àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn lè mọ̀ mí nígbà tí mo bá ti ipasẹ̀ ìwọ Gogu fi bí ìwà mímọ́ mi ti rí hàn níṣojú wọn.

17 OLUWA ní: ṣé ìwọ ni ẹni tí mo sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ní ìgbà àtijọ́ láti ẹnu àwọn wolii Israẹli, àwọn iranṣẹ mi, tí wọ́n ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún ọpọlọpọ ọdún pé n óo mú ọ wá láti gbógun tì wọ́n?

Ìyà Tí Ọlọrun Fi Jẹ Gogu

18 “Ṣugbọn ní ọjọ́ tí Gogu bá gbógun ti ilẹ̀ Israẹli, inú mi óo ru. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

19 Pẹlu ìtara ati ìrúnú ni mo fi ń sọ pé ilẹ̀ Israẹli yóo mì tìtì ní ọjọ́ náà.

20 Àwọn ẹja inú omi, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run, àwọn ẹranko inú igbó, gbogbo ohun tí ń rìn lórí ilẹ̀, ati gbogbo eniyan tí ó wà láyé yóo wárìrì. Àwọn òkè yóo wó lulẹ̀, àwọn òkè etí òkun yóo ṣubú sinu òkun. Gbogbo odi ìlú yóo sì wó lulẹ̀.

21 N óo dá oríṣìíríṣìí ẹ̀rù ba Gogu, lórí òkè mi, àwọn ọmọ ogun rẹ̀ yóo fa idà yọ sí ara wọn. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

22 N óo sì fi àjàkálẹ̀ àrùn ati ikú ogun ṣe ìdájọ́ wọn. N óo rọ òjò yìnyín, iná, ati imí ọjọ́ lé òun, ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀, ati ọpọlọpọ eniyan pupọ tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ lórí.

23 N óo fi títóbi mi ati ìwà mímọ́ mi hàn lójú àwọn orílẹ̀-èdè, wọn yóo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA.”

Categories
ISIKIẸLI

ISIKIẸLI 39

A Ṣẹgun Gogu

1 OLUWA Ọlọrun ní, “Ìwọ ọmọ eniyan, fi àsọtẹ́lẹ̀ bá Gogu wí, sọ fún un pé OLUWA Ọlọrun ní: ‘Mo lòdì sí ọ́, ìwọ Gogu, ìwọ tí o jẹ́ olórí Meṣeki ati Tubali.

2 N óo yí ọ pada, n óo lé ọ siwaju, n óo mú ọ wá láti òpin ìhà àríwá, o óo wá dojú kọ àwọn òkè Israẹli.

3 Lẹ́yìn náà, n óo gbọn ọrun rẹ dànù lọ́wọ́ òsì rẹ; n óo sì gbọn ọfà bọ́ sílẹ̀ lọ́wọ́ ọ̀tún rẹ.

4 Ìwọ, ati gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ, ati àwọn eniyan tí wọ́n wà pẹlu rẹ yóo kú lórí àwọn òkè Israẹli. N óo fi yín ṣe oúnjẹ fún oniruuru àwọn ẹyẹ ati àwọn ẹranko burúkú.

5 Ninu pápá tí ó tẹ́jú ni ẹ óo kú sí; èmi OLUWA Ọlọrun, ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

6 N óo rọ òjò iná lé Magogu lórí, ati àwọn tí wọn ń gbé láìléwu ní etí òkun, wọn yóo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA.

7 N óo sọ orúkọ mímọ́ mi di mímọ̀ láàrin àwọn eniyan mi àwọn ọmọ Israẹli, n kò ní jẹ́ kí wọ́n ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́ mọ́, àwọn orílẹ̀-èdè yòókù yóo sì mọ̀ pé èmi OLUWA, ni Ẹni Mímọ́ Israẹli.’ ”

8 OLUWA Ọlọrun ní, “Ẹ wò ó! Ọjọ́ tí mo ti sọ̀rọ̀ rẹ̀ ń bọ̀, yóo dé.

9 Àwọn ará ìlú Israẹli yóo tú síta, wọn yóo dáná sun àwọn ohun ìjà ogun: apata ati asà, ọrun ati ọfà, àáké ati ọ̀kọ̀. Ọdún meje ni wọn yóo fi dáná sun wọ́n.

10 Fún ọdún meje yìí, ẹnìkan kò ní ṣẹ́ igi ìdáná lóko, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní gé igi ninu igbó kí wọ́n tó dáná; ohun ìjà ogun ni wọn yóo máa fi dáná. Wọn yóo kó ẹrù àwọn tí wọ́n ti kó wọn lẹ́rù rí; wọn yóo fi ogun kó àwọn ìlú tí wọ́n ti fi ogun kó wọn rí. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

Ìsìnkú Gogu

11 OLUWA ní, “Tí ó bá di ìgbà náà, n óo fún Gogu ní ibi tí wọn yóo sin ín sí ní Israẹli, àní àfonífojì àwọn arìnrìnàjò tí ó wà ní ìlà oòrùn Òkun Iyọ̀. Yóo dínà mọ́ àwọn arìnrìnàjò nítorí níbẹ̀ ni a óo sin Gogu ati gbogbo àwọn eniyan rẹ̀ sí. A óo sì máa pè é ní àfonífojì Hamoni Gogu.

12 Oṣù meje ni yóo gba àwọn ọmọ Israẹli láti sin òkú wọn, kí wọ́n baà lè fọ ilẹ̀ náà mọ́.

13 Gbogbo àwọn tí ń gbé ilẹ̀ náà ni yóo sin wọ́n, wọn óo sì gbayì ní ọjọ́ náà, nígbà tí mo bá fi ògo mi hàn. OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.

14 Lẹ́yìn oṣù meje wọn yóo yan àwọn kan tí wọn óo la ilẹ̀ náà já, tí wọn óo máa wá òkú tí ó bá kù nílẹ̀, tí wọn óo sì máa sin wọ́n kí wọ́n lè sọ ilẹ̀ náà di mímọ́.

15 Bí ẹnìkan ninu àwọn tí ń wá òkú kiri bá rí egungun eniyan níbìkan, yóo fi àmì sibẹ títí tí àwọn tí ń sin òkú yóo fi wá sin ín ní àfonífojì Hamoni Gogu.

16 Ìlú kan yóo wà níbẹ̀ tí yóo máa jẹ́ Hamoni. Bẹ́ẹ̀ ni wọn yóo ṣe fọ ilẹ̀ náà mọ́.”

17 OLUWA Ọlọrun ní, “Ìwọ ọmọ eniyan, ké pe oniruuru ẹyẹ ati gbogbo ẹranko igbó, kí o sọ fún wọn pé, ‘Ẹ gbá ara yín jọ, kí ẹ máa bọ̀ láti gbogbo àyíká tí ẹ wà. Ẹ wá sí ibi ẹbọ ńlá tí mo fẹ́ ṣe fun yín lórí àwọn òkè Israẹli. Ẹ óo jẹ ẹran, ẹ óo sì mu ẹ̀jẹ̀.

18 Ẹ óo jẹ ẹran ara àwọn akikanju, ẹ óo sì mu ẹ̀jẹ̀ àwọn ọba ilẹ̀ ayé, bíi ti àgbò, ati ọ̀dọ́ aguntan, ati ewúrẹ́ ati àwọn mààlúù rọ̀bọ̀tọ̀ Baṣani.

19 Ẹ óo jẹ ọ̀rá ní àjẹyó, ẹ óo sì mu ẹ̀jẹ̀ ní àmuyó ní ibi àsè tí n óo sè fun yín.

20 Ẹ óo jẹ ẹṣin ati àwọn tí wọn ń gùn wọ́n, àwọn alágbára ati oríṣìíríṣìí àwọn ọmọ ogun níbi àsè tí n óo sè fun yín.’ Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

Ìràpadà Israẹli

21 “N óo fi ògo mi hàn láàrin àwọn orílẹ̀-èdè, gbogbo wọn ni yóo sì rí irú ẹjọ́ tí mo dá wọn ati irú ìyà tí mo fi jẹ wọ́n.

22 Láti ìgbà náà lọ, àwọn ọmọ Israẹli óo mọ̀ pé èmi ni OLUWA Ọlọrun wọn.

23 Àwọn orílẹ̀-èdè yóo sì mọ̀ pé ẹ̀ṣẹ̀ ni àwọn ọmọ Israẹli dá tí wọ́n fi di ẹni tí ó lọ sí ìgbèkùn, ati pé wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí mi ni mo ṣe dijú sí wọn, tí mo fi wọ́n lé àwọn ọ̀tá wọn lọ́wọ́, tí wọ́n sì fi idà pa wọ́n.

24 Bí àìmọ́ ati ẹ̀ṣẹ̀ wọn ti pọ̀ tó, bẹ́ẹ̀ ni mo fìyà jẹ wọ́n tó, mo sì gbé ojú mi kúrò lọ́dọ̀ wọn.”

25 Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun ní, “N óo ṣàánú gbogbo àwọn ọmọ Israẹli n óo kó àwọn ọmọ Jakọbu pada láti oko ẹrú, n óo ṣàánú gbogbo àwọn ọmọ Israẹli, n óo sì jowú nítorí orúkọ mímọ́ mi.

26 Wọn yóo gbàgbé ìtìjú wọn ati ìwà ọ̀tẹ̀ tí wọn hù sí mi, nígbà tí wọn bá ń gbé orí ilẹ̀ wọn láìléwu, tí kò sì sí ẹni tí yóo dẹ́rùbà wọ́n.

27 Nígbà tí mo bá kó wọn pada láti inú oríṣìíríṣìí orílẹ̀-èdè, tí mo kó wọn jọ láti ilẹ̀ àwọn ọ̀tá wọn, n óo fi ara mi hàn bí ẹni mímọ́ lójú ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè.

28 Wọn óo wá mọ̀ nígbà náà pé èmi ni OLUWA Ọlọrun wọn, nítorí pé mo kó wọn lọ sí ìgbèkùn láàrin àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, mo sì tún kó wọn pada sí ilẹ̀ wọn. N kò ní fi ọ̀kankan ninu wọn sílẹ̀ sí ààrin orílẹ̀-èdè mìíràn mọ́.

29 N óo tú ẹ̀mí mi lé àwọn ọmọ Israẹli lórí, n ko ní gbé ojú mi kúrò lọ́dọ̀ wọn mọ́. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”