Categories
ISIKIẸLI

ISIKIẸLI 20

Ìfẹ́ OLUWA ati Àìbìkítà Eniyan

1 Ní ọjọ́ kẹwaa oṣù karun-un, ọdún keje tí a ti wà ní ìgbèkùn, àwọn àgbààgbà Israẹli kan wá láti wádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ OLUWA, wọ́n sì jókòó níwájú mi.

2 OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní,

3 “Ìwọ ọmọ eniyan sọ fún àwọn àgbààgbà Israẹli pé, OLUWA Ọlọrun ní, ‘Ṣé ẹ wá wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ mi ni? Mo fi ara mi búra pé, n kò ní da yín lóhùn. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.’

4 “Ṣé o óo ṣe ìdájọ́ wọn? Ìwọ ọmọ eniyan, ṣé o óo ṣe ìdájọ́ wọn? Jẹ́ kí wọ́n mọ àwọn nǹkan ìríra tí àwọn baba wọn ṣe.

5 Kí o sì sọ fún wọn pé èmi OLUWA ní, ní ọjọ́ tí mo yan Israẹli, mo búra fún àwọn ọmọ Jakọbu, mo fi ara mi hàn fún wọn ní ilẹ̀ Ijipti, mo sì búra fún wọn pé èmi ni OLUWA Ọlọrun wọn.

6 Ní ọjọ́ náà, mo búra fún wọn pé n óo yọ wọ́n kúrò ni ilẹ̀ Ijipti, n óo sì mú wọn dé ilẹ̀ tí mo ti wá sílẹ̀ fún wọn, ilẹ̀ tí ó kún fún wàrà ati oyin, ilẹ̀ tí ó lógo jùlọ láàrin gbogbo ilẹ̀ ayé.

7 Mo wí fún wọn pé kí olukuluku kọ àwọn nǹkan ẹ̀gbin tí ó gbójú lé sílẹ̀, kí ẹ má sì fi àwọn oriṣa ilẹ̀ Ijipti, ba ara yín jẹ́; nítorí pé èmi ni OLUWA Ọlọrun yín.

8 Ṣugbọn wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí mi, wọn kò sì gbọ́ tèmi, ẹnìkankan ninu wọn kò mójú kúrò lára àwọn ère tí wọ́n ń bọ tẹ́lẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò kọ àwọn oriṣa Ijipti sílẹ̀. Mo kọ́ rò ó pé kí n bínú sí wọn, kí n sì tẹ́ ibinu mi lọ́rùn lára wọn ní ilẹ̀ Ijipti.

9 Ṣugbọn mo tún ro ti orúkọ mi, nítorí n kò fẹ́ kí wọ́n ba orúkọ mi jẹ́ láàrin àwọn eniyan tí wọn ń gbé, lójú àwọn tí mo ti fi ara mi hàn wọ́n ní ilẹ̀ Ijipti, nígbà tí mo kó wọn jáde kúrò níbẹ̀.

10 “Nítorí náà, mo kó wọn kúrò ní ilẹ̀ Ijipti, wá sinu aṣálẹ̀.

11 Mo fún wọn ní òfin mi, mo sì fi ìlànà mi hàn wọ́n, èyí tí ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀lé yóo yè.

12 Lẹ́yìn náà, mo fún wọn ní ọjọ́ ìsinmi, kí ó máa jẹ́ àmì láàrin èmi pẹlu wọn, kí wọ́n lè mọ̀ pé èmi OLUWA yà wọ́n sí mímọ́.

13 Ṣugbọn àwọn ọmọ Israẹli dìtẹ̀ sí mi ninu aṣálẹ̀, wọn kò pa òfin mi mọ́; wọ́n sì kọ ìlànà mi sílẹ̀, èyí tí ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀lé yóo yè. Wọ́n ba ọjọ́ ìsinmi mi jẹ́ patapata. Lẹ́yìn náà mo kọ́ gbèrò ati fi ibinu pa wọ́n run patapata ninu aṣálẹ̀.

14 Ṣugbọn mo tún ro ti orúkọ mi, nítorí n kò fẹ́ kí wọ́n ba orúkọ mi jẹ́ lójú àwọn orílẹ̀-èdè tí mo ti kó wọn jáde.

15 Nítorí náà, mo búra fún wọn ninu aṣálẹ̀ pé n kò ní mú wọn dé ilẹ̀ tí mo ti ṣèlérí pé n óo fún wọn, ilẹ̀ tí ó kún fún wàrà ati oyin, ilẹ̀ tí ó lógo jù ní gbogbo ilẹ̀ ayé.

16 Nítorí pé wọ́n kọ ìlànà mi sílẹ̀, wọn kò tẹ̀lé òfin mi, wọ́n sì ba ọjọ́ ìsinmi mi jẹ́, nítorí pé ọkàn wọn kò kúrò lọ́dọ̀ àwọn oriṣa wọn.

17 “Sibẹsibẹ mo fojú àánú wò wọ́n, n kò pa wọ́n run sinu aṣálẹ̀.

18 Mo sọ fún àwọn ọmọ wọn ninu aṣálẹ̀ pé kí wọ́n má tọ ọ̀nà tí àwọn baba wọn rìn, kí wọ́n má ṣe tẹ̀lé òfin wọn, tabi kí wọ́n bọ oriṣa wọn.

19 Mo ní èmi OLUWA ni Ọlọrun yín. Ẹ máa rìn ní ọ̀nà mi, kí ẹ sì máa pa òfin mi mọ́.

20 Ẹ máa pa àwọn ọjọ́ ìsinmi mi mọ́, kí wọ́n lè jẹ́ àmì láàrin èmi pẹlu yín, kí ẹ lè mọ̀ pé èmi OLUWA ni Ọlọrun yín.

21 “Ṣugbọn, àwọn ọmọ náà ṣọ̀tẹ̀ sí mi: wọn kò tẹ̀lé ìlànà mi, wọn kò sì fi tọkàntọkàn pa òfin mi mọ́, èyí tí ó jẹ́ pé bí eniyan bá tẹ̀lé ni yóo yè, wọ́n sì tún ba ọjọ́ ìsinmi mi jẹ́. Lẹ́yìn náà mo kọ́ gbèrò ati fi ibinu pa wọ́n run patapata, kí n tẹ́ ibinu mi lọ́rùn lórí wọn ninu aṣálẹ̀.

22 Ṣugbọn mo rowọ́, mo sì ro ti orúkọ mi, tí n kò fẹ́ kí wọ́n bàjẹ́ lójú àwọn orílẹ̀-èdè tí mo ti kó wọn jáde.

23 Nítorí náà, mo ṣe ìlérí fún wọn ninu aṣálẹ̀ pé n óo fọ́n wọn káàkiri láàrin àwọn orílẹ̀-èdè yòókù,

24 nítorí pé wọn kò pa òfin mi mọ́, kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n kọ ìlànà mi sílẹ̀, wọ́n ba ọjọ́ ìsinmi mi jẹ́, wọn kò sì mójú kúrò lára àwọn oriṣa tí àwọn baba wọn ń bọ.

25 “Nítorí náà, mo fún wọn ní àṣẹ tí kò dára ati ìlànà tí kò lè gbà wọ́n là.

26 Mo jẹ́ kí ẹbọ wọn sọ wọ́n di aláìmọ́, mọ jẹ́ kí wọ́n máa sun àkọ́bí wọn ninu iná, kí ìpayà lè bá wọn, kí wọ́n lè mọ̀ pé èmi ni OLUWA.

27 “Nítorí náà, ìwọ ọmọ eniyan, sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé èmi OLUWA Ọlọrun ní Ọ̀nà mìíràn tí àwọn baba yín tún fi bà mí lórúkọ jẹ́ ni pé wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí mi.

28 Nígbà tí mo mú wọn dé ilẹ̀ tí mo búra pé n óo fún wọn, bí wọ́n bá ti rí òkè kan tí ó ga, tabi tí wọ́n rí igi kan tí ewé rẹ̀ pọ̀, wọn a bẹ̀rẹ̀ sí gbé ẹbọ wọn kalẹ̀ sibẹ. Wọn a rú ẹbọ ìríra, wọn a mú kí òórùn dídùn ẹbọ wọn bo gbogbo ibẹ̀, wọ́n a sì bẹ̀rẹ̀ sí ta ohun mímu sílẹ̀.

29 Mo bi wọ́n léèrè pé irú ibi pẹpẹ ìrúbọ wo ni ẹ tilẹ̀ ń lọ ríì? Nítorí náà ni wọ́n ṣe ń pe ibẹ̀ ní Bamatítí di òní.

30 Nítorí náà, sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé èmi OLUWA Ọlọrun ní ṣé ẹ óo máa ba ara yín jẹ́ gẹ́gẹ́ bí àwọn baba yín, ẹ óo sì máa ṣìnà tẹ̀lé àwọn nǹkan ìríra wọn?

31 Ẹ̀ ń rú àwọn ẹbọ yín, ẹ sì ń fi àwọn ọmọkunrin yín rú ẹbọ sísun, ẹ sì ti fi oriṣa bíbọ ba ara yín jẹ́ títí di òní. Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ṣé ẹ óo tún máa wá wádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ mi? Mo fi ara mi búra pé, ẹ kò ní rídìí ọ̀rọ̀ kankan lọ́dọ̀ mi.

32 Èrò ọkàn yín kò ní ṣẹ: ẹ̀ ń gbèrò ati dàbí àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn ati àwọn ẹ̀yà tí ó wà ní agbègbè yín, kí ẹ máa bọ igi ati òkúta.

Ọlọrun a máa Fi Ìyà Jẹ Ẹlẹ́ṣẹ̀ a sì máa Dáríjì

33 “Mo fi ara mi búra, dájúdájú, tipátipá, pẹlu ibinu ati ọwọ́ líle ni n óo fi jọba lórí yín.

34 N óo ko yín jáde láàrin àwọn orílẹ̀-èdè, n óo ko yín jọ láti gbogbo ilẹ̀ tí mo ti fi tipátipá fọ́n yín ká sí, pẹlu ọwọ́ líle, ati ibinu.

35 N óo ko yín lọ sinu aṣálẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, níbẹ̀ ni n óo ti dájọ́ yín lojukooju.

36 Bí mo ṣe dájọ́ àwọn baba ńlá yín ní aṣálẹ̀ ilẹ̀ Ijipti ni n óo dájọ́ yín. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

37 “N óo mú kí ẹ gba abẹ́ ọ̀pá mi kọjá, n óo sì mu yín wá sí abẹ́ ìdè majẹmu.

38 N óo ṣa àwọn ọlọ̀tẹ̀ ati àwọn tí ń ṣe oríkunkun sí mi kúrò láàrin yín. N óo mú wọn kúrò ní ilẹ̀ tí wọ́n ti jẹ́ àlejò, ṣugbọn wọn kò ní dé ilẹ̀ Israẹli. Ẹ óo wá mọ̀ nígbà náà pé èmi ni OLUWA.”

39 Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, OLUWA Ọlọrun ní, “Kí olukuluku yín lọ máa bọ oriṣa rẹ̀ láti ìsinsìnyìí lọ, bí ẹ kò bá fẹ́ gbọ́ tèmi, ṣugbọn ẹ kò ní fi ẹbọ ati oriṣa yín ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́ mọ́.

40 Lórí òkè mímọ́ mi, lórí òkè gíga Israẹli, ni gbogbo ẹ̀yin ọmọ ilé Israẹli yóo ti máa sìn mí. Gbogbo yín pátá ní ilẹ̀ náà, ni ẹ óo máa sìn mí níbẹ̀. N óo yọ́nú si yín. N óo sì bèèrè ọrẹ àdájọ lọ́wọ́ yín ati ọrẹ àtinúwá tí ó dára jùlọ pẹlu ẹbọ mímọ́ yín.

41 N óo yọ́nú si yín bí ìgbà tí mo bá gbọ́ òórùn ẹbọ dídùn, nígbà tí mo bá ń ko yín jáde kúrò láàrin àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, tí mò ń ko yín jọ kúrò láàrin gbogbo orílẹ̀-èdè tí ẹ fọ́nká sí. Ẹwà mímọ́ mi yóo sì hàn lára yín lójú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí ó kù.

42 Ẹ óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA nígbà tí mo bá ko yín dé ilẹ̀ Israẹli, ilẹ̀ tí mo búra láti fún àwọn baba ńlá yín.

43 Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ náà, ẹ óo ranti ìṣe yín, ati gbogbo ìwà èérí tí ẹ hù tí ẹ fi ba ara yín jẹ́. Ojú ara yín yóo sì tì yín nígbà tí ẹ bá ranti gbogbo nǹkan burúkú tí ẹ ti ṣe.

44 Ẹ óo mọ̀ pé èmi ni OLUWA nígbà tí mo bá ba yín wí nítorí orúkọ mi, tí kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí ìwà burúkú yín tabi gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà burúkú yín, ẹ̀yin ọmọ Israẹli, èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

Iná Yóo Jó Ní gúsù

45 OLUWA sọ fún mi pé,

46 “Ìwọ ọmọ eniyan, kọjú sí ìhà gúsù, fi iwaasu bá ìhà ibẹ̀ wí, kí o sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa àwọn ilẹ̀ igbó Nẹgẹbu.

47 Sọ fún igbó ibẹ̀ pé èmi OLUWA Ọlọrun ní n óo sọ iná sí i, yóo sì jó gbogbo àwọn igi inú rẹ̀, ati tútù ati gbígbẹ, iná náà kò ní kú. Yóo jó gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní gúsù títí dé àríwá.

48 Gbogbo eniyan ni yóo rí i pé èmi OLUWA ni mo dá iná náà, kò sì ní ṣe é pa.”

49 Mo bá dáhùn pé, “Áà! OLUWA Ọlọrun, wọ́n ń sọ nípa mi pé, ‘Ǹjẹ́ òun fúnrarẹ̀ kọ́ ni ó ń ro òwe yìí, tí ó sì ń pa á mọ́ wa?’ ”

Categories
ISIKIẸLI

ISIKIẸLI 21

Idà OLUWA

1 OLUWA bá mi sọ̀rọ̀; ó ní,

2 “Ìwọ ọmọ eniyan, kọjú sí Jerusalẹmu kí o sọ àsọtẹ́lẹ̀ sí ibi mímọ́ Israẹli. Sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ilẹ̀ Israẹli.

3 Sọ fún ilẹ̀ náà pé OLUWA ní, ‘Wò ó, mo ti dojú kọ ọ́, n óo yọ idà mi ninu àkọ̀ rẹ̀, n óo sì pa àwọn eniyan inú rẹ: ati àwọn eniyan rere ati àwọn eniyan burúkú.

4 N óo pa àwọn eniyan rere ati àwọn eniyan burúkú tí ó wà ninu rẹ run, nítorí náà, n óo yọ idà mi ninu àkọ̀ rẹ̀, n óo sì bẹ̀rẹ̀ sí pa gbogbo eniyan láti ìhà gúsù títí dé ìhà àríwá.

5 Gbogbo eniyan yóo sì mọ̀ pé èmi OLUWA ni mo fa idà mi yọ, n kò sì ní dá a pada sinu àkọ̀ mọ́.’

6 “Ìwọ ọmọ eniyan, máa mí ìmí ẹ̀dùn, bí ẹni tí ọkàn rẹ̀ ti dàrú, tí ó sì ń kẹ́dùn níwájú wọn.

7 Bí wọ́n bá bi ọ́ pé kí ló dé tí o fi ń mí ìmí ẹ̀dùn, sọ fún wọn pé nítorí ìròyìn tí o gbọ́ ni. Nígbà tí ó bá ṣẹlẹ̀, ọkàn gbogbo eniyan yóo dàrú, ọwọ́ wọn yóo rọ ìrẹ̀wẹ̀sì yóo dé bá wọn, ẹsẹ̀ wọn kò ní ranlẹ̀ mọ́. Wò ó! Yóo ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀, n óo sì mú un ṣẹ. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

8 OLUWA tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní,

9 “Ìwọ ọmọ eniyan, sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé èmi: OLUWA Ọlọrun ní:

Ẹ wo idà, àní idà tí a ti pọ́n, tí a sì ti fi epo pa.

10 A ti pọ́n ọn láti fi paniyan;

a ti fi epo pa á, kí ó lè máa kọ mànà bíi mànàmáná.

Ọ̀rọ̀ yìí kìí ṣe ọ̀rọ̀ àríyá;

nítorí àwọn eniyan mi kọ̀, wọn kò náání ìkìlọ̀ ati ìbáwí mi.

11 Nítorí náà, a pọ́n idà náà, a sì fi epo pa á,

kí á lè fi lé ẹni tí yóo fi paniyan lọ́wọ́.

12 Ìwọ ọmọ eniyan, kígbe, kí o sì pohùnréré ẹkún,

nítorí àwọn eniyan mi ni a yọ idà sí;

ati àwọn olórí ní Israẹli.

Gbogbo wọn ni a óo fi idà pa pẹlu àwọn eniyan mi.

Nítorí náà káwọ́ lérí kí o sì máa hu.

13 Mò ń dán àwọn eniyan mi wò,

bí wọ́n bá sì kọ̀, tí wọn kò ronupiwada,

gbogbo nǹkan wọnyi yóo ṣẹlẹ̀ sí wọn,

Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

14 “Nítorí náà, ìwọ ọmọ eniyan, sọ àsọtẹ́lẹ̀, kí o sápẹ́, fi idà lalẹ̀ léraléra, idà tí a fà yọ tí a fẹ́ fi paniyan. Idà tí yóo pa ọ̀pọ̀ eniyan ní ìpakúpa, tí ó sì súnmọ́ tòsí wọn pẹ́kípẹ́kí.

15 Kí àyà wọn lè já, kí ọpọlọpọ lè kú ní ẹnubodè wọn. Mo ti fi idà tí ń dán lélẹ̀ fún pípa eniyan, ó ń kọ mànà bíi mànàmáná, a sì ti fi epo pa á.

16 Máa pa wọ́n lọ ní ọwọ́ ọ̀tún, ati ní ọwọ́ òsì, níbikíbi tí ó bá sá ti kọjú sí.

17 Èmi náà yóo máa pàtẹ́wọ́, inú tí ń bí mi yóo sì rọ̀, èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

Idà Ọba Babiloni

18 OLUWA tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní:

19 “Ìwọ ọmọ eniyan, la ọ̀nà meji fún idà ọba Babiloni láti gbà wọ̀lú, kí ọ̀nà mejeeji wá láti ilẹ̀ kan náà. Fi atọ́ka sí oríta níbi tí ọ̀nà ti yà wọ ìlú.

20 La ọ̀nà fún idà kan láti gbà wọ ìlú Raba ní ilẹ̀ Amoni, kí o sì la ọ̀nà mìíràn fún idà láti gbà wọ ilẹ̀ Juda ati ìlú Jerusalẹmu tí a mọ odi yíká.

21 Nítorí pé ọba Babiloni ti dúró sí oríta, ní ibi tí ọ̀nà ti pínyà; ó dúró láti ṣe àyẹ̀wò. Ó mi ọfà, ó bá oriṣa sọ̀rọ̀, ó sì woṣẹ́ lára ẹ̀dọ̀ ẹran.

22 Ọfà ìbò Jerusalẹmu yóo bọ́ sí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀. Yóo kígbe, àwọn eniyan náà yóo sì kígbe sókè. Wọn óo gbé igi tí wọ́n fi ń fọ́ ìlẹ̀kùn ti ìlẹ̀kùn bodè rẹ̀, wọn yóo mọ òkítì sí ara odi rẹ̀, wọn yóo sì mọ ilé ìṣọ́ tì í.

23 Gbogbo ohun tí ó ń ṣe yóo dàbí ẹni tí ń dífá irọ́ lójú àwọn ará ìlú, nítorí pé majẹmu tí wọ́n ti dá yóo ti kì wọ́n láyà; ṣugbọn ọba Babiloni yóo mú wọn ranti ẹ̀ṣẹ̀ wọn, yóo ṣẹgun wọn yóo sì kó wọn lọ.

24 Nítorí náà, èmi OLUWA Ọlọrun, ní, ẹ ti jẹ́ kí n ranti ẹ̀ṣẹ̀ yín, nítorí pé ẹ ti tú àṣírí ẹ̀ṣẹ̀ yín, ninu gbogbo ohun tí ẹ̀ ń ṣe ni ẹ̀ṣẹ̀ yín ti hàn; ogun yóo ko yín nítorí pé ẹ ti mú kí n ranti àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín.

25 “Ìwọ olórí Israẹli, aláìmọ́ ati ẹni ibi, ọjọ́ rẹ pé; àkókò ìjìyà ìkẹyìn rẹ sì ti tó.

26 Ẹ ṣí fìlà, kí ẹ sì ṣí adé ọba kúrò lórí, gbogbo nǹkan kò ní wà bí wọ́n ṣe rí. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀. Ẹ gbé àwọn tí ipò wọn rẹlẹ̀ ga, kí ẹ sì rẹ àwọn tí ipò wọn wà lókè sílẹ̀.

27 Ìparun! Ìparun! N óo pa ìlú yìí run ni; ṣugbọn n kò ní tíì pa á run, títí ẹni tí ó ni í yóo fi dé, tí n óo sì fi lé e lọ́wọ́.

Idà ati Àwọn Ará Amoni

28 “Ìwọ ọmọ eniyan, sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé ohun tí èmi OLUWA Ọlọrun sọ nípa àwọn ará Amoni ati ẹ̀gàn wọn nìyí:

‘A ti fa idà yọ, láti paniyan.

A ti fi epo pa á kí ó lè máa dán, kí ó sì máa kọ mànà bíi mànàmáná.

29 Nígbà tí wọn ń ríran èké, tí wọ́n sì ń woṣẹ́ irọ́ fún ọ, a óo gbé idà náà lé ọrùn àwọn aláìmọ́ ati ẹni ibi, tí ọjọ́ wọn ti pé, àní ọjọ́ ìjìyà ìkẹyìn wọn.

30 “ ‘Dá idà náà pada sinu àkọ̀ rẹ̀. Ní ilẹ̀ rẹ ní ibi tí a ti dá ọ, ni n óo ti dá ọ lẹ́jọ́.

31 N óo bínú sí ọ lọpọlọpọ, ìrúnú mi yóo jó ọ bí iná, n óo fà ọ́ lé àwọn oníjàgídíjàgan lọ́wọ́, àwọn tí wọ́n mọ̀ bí wọ́n ṣe ń panirun.

32 O óo di nǹkan ìdáná, lórí ilẹ̀ yín ni a óo pa yín sí, ẹ óo sì di ẹni ìgbàgbé, èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.’ ”

Categories
ISIKIẸLI

ISIKIẸLI 22

Ìwà Ibi Jerusalẹmu

1 OLUWA tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní:

2 “Ìwọ ọmọ eniyan, ṣé o óo dájọ́, ṣé o óo dájọ́ ìlú tí ó kún fún ìpànìyàn yìí? Sọ gbogbo ìwà ìríra rẹ̀ fún un.

3 Sọ fún un pé èmi OLUWA Ọlọrun ní, ìwọ ìlú tí wọ́n ti ń paniyan ní ìpakúpa kí àkókò ìjìyà rẹ̀ lè tètè dé, ìlú tí ń fi oriṣa ba ara rẹ̀ jẹ́!

4 A ti dá ọ lẹ́bi nítorí àwọn eniyan tí o pa, o sì ti di aláìmọ́ nítorí àwọn ère tí o gbẹ́. O ti mú kí ọjọ́ ìjìyà rẹ súnmọ́ tòsí, ọdún tí a dá fún ọ sì pé tán. Nítorí náà, mo ti sọ ọ́ di ẹni ẹ̀gàn láàrin àwọn eniyan, ati ẹni yẹ̀yẹ́ lójú gbogbo orílẹ̀-èdè.

5 Àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n súnmọ́ ọ ati àwọn tí wọ́n jìnnà sí ọ yóo máa fi ọ́ ṣe yẹ̀yẹ́, ìwọ tí o kò níyì, tí o kún fún ìdàrúdàpọ̀.

6 Wo àwọn olórí ní ilẹ̀ Israẹli tí wọ́n wà ninu rẹ, olukuluku ti pinnu láti máa lo agbára rẹ̀ láti máa paniyan.

7 Àwọn ọmọ kò náání baba ati ìyá wọn ninu rẹ; wọ́n sì ń ni àwọn àjèjì ninu rẹ lára; wọ́n sì ń fìyà jẹ àwọn aláìníbaba ati opó.

8 O kò bìkítà fún àwọn ohun mímọ́ mi, o sì ti ba ọjọ́ ìsinmi mi jẹ́.

9 Àwọn eniyan inú rẹ ń parọ́ láti paniyan. Wọ́n ń jẹbọ kiri lórí àwọn òkè ńláńlá, wọ́n sì ń ṣe ohun ìtìjú.

10 Àwọn mìíràn ń bá aya baba wọn lòpọ̀, wọ́n sì ń fi ipá bá obinrin lòpọ̀ ní ìgbà tí ó ń ṣe nǹkan oṣù rẹ̀ lọ́wọ́.

11 Ẹnìkínní ń bá aya ẹnìkejì rẹ̀ lòpọ̀; àwọn kan ń bá aya ọmọ wọn lòpọ̀; ẹ̀gbọ́n ń bá àbúrò rẹ̀ lòpọ̀, àwọn mìíràn sì ń bá ọbàkan wọn lòpọ̀ ninu rẹ, Jerusalẹmu.

12 Wọ́n ń gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ láti paniyan láàrin ìlú, wọ́n ń gba owó èlé, ẹ̀ ń ní àníkún, ẹ sì ń fi ipá gba owó lọ́wọ́ aládùúgbò yín, ẹ ti gbàgbé mi, èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

13 “Nítorí náà mo pàtẹ́wọ́ le yín lórí nítorí èrè aiṣootọ tí ẹ̀ ń jẹ ati eniyan tí ẹ̀ ń pa ninu ìlú.

14 Ǹjẹ́ o lè ní ìgboyà ati agbára ní ọjọ́ tí n óo bá jẹ ọ́ níyà. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀; bẹ́ẹ̀ ni n óo sì ṣe.

15 N óo fọn yín káàkiri ààrin àwọn àjèjì; n óo tu yín ká sí ààrin àwọn orílẹ̀-èdè, n óo fi òpin sí ìwà èérí tí ẹ̀ ń hù ní Jerusalẹmu.

16 N óo di ẹni ìdọ̀tí lójú àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn nítorí rẹ, o óo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA.”

Ọlọrun Ṣe Àtúnṣe

17 OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní:

18 “Ìwọ ọmọ eniyan; àwọn ọmọ Israẹli ti di ìdàrọ́ lójú mi. Wọ́n dàbí idẹ, páànù, irin, ati òjé tí ó wà ninu iná alágbẹ̀dẹ. Wọ́n dàbí ìdàrọ́ ara fadaka.

19 Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun ní níwọ̀n ìgbà tí gbogbo yín ti di ìdàrọ́, n óo ko yín jọ sí ààrin Jerusalẹmu.

20 Bí eniyan ṣe ń kó fadaka, idẹ, irin, òjé ati páànù pọ̀ sinu ìkòkò lórí iná alágbẹ̀dẹ, kí wọ́n lè yọ́, bẹ́ẹ̀ ni n óo fi ibinu ati ìrúnú ko yín jọ n óo sì yọ yín.

21 N óo ko yín jọ, n óo fẹ́ ìrúnú mi si yín lára bí iná, ẹ óo sì yọ́.

22 Bí wọn tí ń yọ́ fadaka ninu iná alágbẹ̀dẹ, bẹ́ẹ̀ ni n óo fi ibinu yọ yín, ẹ óo sì mọ̀ pé èmi OLUWA ni mo bínú si yín.”

Ẹ̀ṣẹ̀ Àwọn Olórí Israẹli

23 OLUWA tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní,

24 “Ìwọ ọmọ eniyan, sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé ilẹ̀ tí kò mọ́ ni ilẹ̀ wọn, ilẹ̀ tí òjò kò rọ̀ sí lákòókò ibinu èmi OLUWA.

25 Àwọn olórí tí wọ́n wà nílùú dàbí kinniun tí ń bú, tí ó sì ń fa ẹran ya. Wọ́n ti jẹ àwọn eniyan run, wọ́n ń fi ipá já ohun ìní ati àwọn nǹkan olówó iyebíye gbà, wọ́n ti sọ ọpọlọpọ obinrin di opó nílùú.

26 Àwọn alufaa rẹ̀ ti kọ òfin mi sílẹ̀, wọ́n ti sọ ibi mímọ́ mi di aláìmọ́. Wọn kò fi ìyàtọ̀ sáàrin àwọn nǹkan mímọ́ ati nǹkan àìmọ́; wọn kò sì kọ́ àwọn eniyan ní ìyàtọ̀ tí ó wà láàrin nǹkan mímọ́ ati àìmọ́. Wọn kò bìkítà fún ọjọ́ ìsinmi mi, mo sì ti di aláìmọ́ láàrin wọn.

27 Àwọn olórí tí ó wà ninu wọn dàbí ìkookò tí ń fa ẹran ya, wọ́n ń pa eniyan, wọ́n sì ń run eniyan láti di olówó.

28 Àwọn wolii wọn ń tàn wọ́n, wọ́n ń ríran irọ́, wọ́n ń woṣẹ́ èké. Wọ́n ń wí pé, OLUWA sọ báyìí, báyìí; bẹ́ẹ̀ sì ni OLUWA kò sọ nǹkankan.

29 Àwọn eniyan ilẹ̀ náà ń fi ipá gba nǹkan-oní-nǹkan; wọ́n ń ni talaka ati aláìní lára, wọ́n sì ń fi ipá gba nǹkan lọ́wọ́ àwọn àlejò láì ṣe àtúnṣe.

30 Mo wá ẹnìkan láàrin wọn tí ìbá tún odi náà mọ, kí ó sì dúró níbi tí odi ti ya níwájú mi láti bẹ̀bẹ̀ fún ilẹ̀ náà, kí n má baà pa á run, ṣugbọn n kò rí ẹnìkan.

31 Nítorí náà, n óo bínú sí wọn; n óo fi ìrúnú pa wọ́n rẹ́, n óo sì gbẹ̀san ìwà wọn lára wọn. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

Categories
ISIKIẸLI

ISIKIẸLI 23

Àwọn Arabinrin Tí Wọ́n Jẹ́ Ẹlẹ́ṣẹ̀

1 OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní,

2 “Ìwọ ọmọ eniyan, àwọn ọmọbinrin meji kan wà, tí wọ́n jẹ́ ọmọ ìyá kan náà.

3 Wọ́n lọ ṣe aṣẹ́wó ní ilẹ̀ Ijipti nígbà tí wọ́n jẹ́ ọmọge. Àwọn kan fọwọ́ fún wọn lọ́mú, wọ́n fọwọ́ pa orí ọmú wọn nígbà tí wọn kò tíì mọ ọkunrin.

4 Orúkọ ẹ̀gbọ́n ń jẹ́ Ohola, ti àbúrò sì ń jẹ́ Oholiba. Àwọn mejeeji di tèmi; wọ́n sì bímọ lọkunrin ati lobinrin. Èyí tí ń jẹ́ Ohola ni Samaria, èyí tí ń jẹ́ Oholiba ni Jerusalẹmu.

5 Ohola tún lọ ṣe àgbèrè lẹ́yìn tí ó ti di tèmi, ó tún ń ṣẹ́jú sí àwọn ará Asiria, olólùfẹ́ rẹ̀:

6 àwọn ọmọ ogun tí wọn ń wọ aṣọ àlàárì, àwọn gomina ati àwọn ọ̀gágun, ati àwọn ẹlẹ́ṣin, ọdọmọkunrin ni gbogbo wọn, ojú wọn sì fanimọ́ra.

7 Ó bá gbogbo àwọn eniyan pataki pataki Asiria ṣe àgbèrè, ó sì fi oriṣa gbogbo àwọn tí ó ń ṣẹ́jú sí ba ara rẹ̀ jẹ́.

8 Kò kọ ìwà àgbèrè rẹ̀ tí ó ń hù nígbà tí ó ti wà ní ilẹ̀ Ijipti sílẹ̀. Nígbà èwe rẹ̀, àwọn ọkunrin bá a lòpọ̀, wọ́n fọwọ́ pa á lọ́mú, wọ́n sì tẹ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ wọn lọ́rùn lára rẹ̀.

9 Nítorí gbogbo èyí, mo fi lé àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́, àwọn ará Asiria tí ó ń ṣẹ́jú sí.

10 Wọ́n tú aṣọ lára rẹ̀, wọ́n kó àwọn ọmọ rẹ̀ lọkunrin ati lobinrin; wọ́n sì fi idà pa òun alára. Orúkọ rẹ̀ wá di yẹ̀yẹ́ láàrin àwọn obinrin nígbà tí ìdájọ́ dé bá a.

11 “Oholiba, àbúrò rẹ̀ rí èyí, sibẹsibẹ, ojú ṣíṣẹ́ sí ọkunrin ati àgbèrè tirẹ̀ burú ju ti ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lọ.

12 Ó ń ṣẹ́jú sí àwọn ará Asiria: àwọn gomina ati àwọn ọ̀gágun, àwọn ọmọ ogun tí wọ́n di ihamọra, tí wọn ń gun ẹṣin, ọdọmọkunrin ni gbogbo wọn, ojú wọn fanimọ́ra.

13 Mo rí i pé ó ti ba ara rẹ̀ jẹ́, ọ̀nà kan náà ni àwọn mejeeji jọ ń tọ̀.

14 “Ṣugbọn ìwà àgbèrè tirẹ̀ ju ti ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lọ. Nígbà tí ó rí àwòrán àwọn ọkunrin, ará Kalidea tí a fi ọ̀dà pupa kùn lára ògiri,

15 tí wọ́n di àmùrè, tí wọ́n wé lawani gbọ̀ọ̀rọ̀ gbọ̀ọ̀rọ̀, tí gbogbo wọn dàbí ọ̀gá àwọn oníkẹ̀kẹ́ ogun, àwọn ọmọ ogun ará Babilonia.

16 Bí ó ti rí wọn, wọ́n wọ̀ ọ́ lójú, ó bá rán ikọ̀ sí wọn ní ilẹ̀ Kalidea.

17 Àwọn ará Babiloni bá tọ̀ ọ́ wá, wọ́n bá a ṣeré ìfẹ́ lórí ibùsùn rẹ̀, wọ́n sì fi ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ wọn bà á jẹ́. Nígbà tí wọ́n bà á jẹ́ tán, ó kúrò lọ́dọ̀ wọn pẹlu ìríra.

18 Nígbà tí ó ń ṣe àgbèrè ní gbangba, tí ó sì tú ara rẹ̀ sí ìhòòhò, mo yipada kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ pẹlu ìríra, bí mo ti yipada kúrò lọ́dọ̀ ẹ̀gbọ́n rẹ̀.

19 Sibẹ ó tún fi kún ìwà àgbèrè rẹ̀, nígbà tí ó ranti àgbèrè ìgbà èwe rẹ̀ ní ilẹ̀ Ijipti.

20 Ó kún fún ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ fún àwọn ọkunrin tí ojú ara wọn dàbí ti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, nǹkan ọkunrin wọn sì dàbí ti ẹṣin.”

21 O tún fẹ́ láti máa ṣe ìṣekúṣe tí o ṣe nígbà èwe rẹ, tí àwọn ọkunrin Ijipti ń dì mọ́ ọ lẹ́gbẹ̀ẹ́, tí wọ́n sì ń fi ọwọ́ fún ọ ní ọmú ọmọge.

Ìdájọ́ Ọlọrun Lórí Arabinrin Tí ó Jẹ́ Àbúrò

22 Nítorí náà, Oholiba, OLUWA Ọlọrun ní, “Mo ṣetán tí n óo gbé àwọn olùfẹ́ rẹ dìde, àwọn tí o kọ̀ sílẹ̀ nítorí ìríra. N óo mú wọn dojú kọ ọ́ ní gbogbo ọ̀nà:

23 àwọn ará Babiloni ati gbogbo àwọn ará Kalidea láti Pekodi, ati Ṣoa ati Koa, pẹlu gbogbo àwọn ará Asiria: àwọn ọdọmọkunrin tí ojú wọn fanimọ́ra, àwọn gomina, ati àwọn ọ̀gágun, tí gbogbo wọn jẹ́ olórí ogun, tí wọ́n sì ń gun ẹṣin.

24 Wọn óo dojú kọ ọ́ láti ìhà àríwá, pẹlu kẹ̀kẹ́ ogun, kẹ̀kẹ́ ẹrù, ati ogunlọ́gọ̀ àwọn ọmọ ogun. Wọn óo gbógun tì ọ́ ní gbogbo ọ̀nà pẹlu apata, asà ati àkẹtẹ̀ ogun. N óo fi ìdájọ́ rẹ lé wọn lọ́wọ́, òfin ilẹ̀ wọn ni wọn óo sì tẹ̀lé tí wọn óo fi dá ọ lẹ́jọ́.

25 N óo dojú kọ ọ́ pẹlu ibinu, n óo jẹ́ kí wọ́n fi ìrúnú bá ọ jà. Wọn óo gé ọ ní etí ati imú, wọn óo sì fi idà pa àwọn eniyan rẹ tí wọ́n kù. Wọn óo kó àwọn ọmọ rẹ ọkunrin ati obinrin lọ, wọn óo sì dáná sun àwọn tí wọ́n kù.

26 Wọn yóo bọ́ aṣọ lára rẹ; wọn yóo kó gbogbo nǹkan ọ̀ṣọ́ rẹ lọ.

27 Bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe fi òpin sí ìṣekúṣe ati àgbèrè tí o kó ti ilẹ̀ Ijipti wá. O kò ní ṣíjú wo àwọn ará Ijipti mọ́, o kò sì ní ranti wọn mọ́.”

28 OLUWA ní, “Mo ṣetán tí n óo fi ọ́ lé àwọn tí o kórìíra lọ́wọ́, àwọn tí ọkàn rẹ yipada kúrò lọ́dọ̀ wọn pẹlu ìríra.

29 Ìkórìíra ni wọn yóo fi máa bá ọ gbé, wọn yóo kó gbogbo èrè iṣẹ́ ọwọ́ rẹ lọ, wọn yóo sì fi ọ́ sílẹ̀ ní ìhòòhò goloto. Wọn yóo tú ọ sí ìhòòhò, gbogbo ayé yóo sì mọ̀ pé aṣẹ́wó ni ọ́. Ìṣekúṣe ati àgbèrè rẹ ni

30 ó mú èyí wá sórí rẹ, nítorí o ti bá àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn ṣe àgbèrè, o sì ti fi oriṣa wọn ba ara rẹ jẹ́.

31 Ìwà tí ẹ̀gbọ́n rẹ hù ni ìwọ náà ń hù, nítorí náà, ìyà tí mo fi jẹ ẹ̀gbọ́n rẹ ni n óo fi jẹ ìwọ náà.”

32 OLUWA Ọlọrun ní:

“ọpọlọpọ ìyà tí mo fi jẹ ẹ̀gbọ́n rẹ ni n óo fi jẹ ọ́,

wọn óo fi ọ́ rẹ́rìn-ín,

wọn óo sì fi ọ́ ṣẹ̀sín,

nítorí ìyà náà óo pọ̀.

33 Ìyà óo jẹ ọ́ lọpọlọpọ,

ìbànújẹ́ óo sì dé bá ọ.

N óo mú ìpayà ati ìsọdahoro bá ọ,

bí mo ṣe mú un bá Samaria, ẹ̀gbọ́n rẹ.

34 O óo jìyà ní àjẹtẹ́rùn,

tóbẹ́ẹ̀ tí o óo máa fi àkúfọ́ àwo ìyà tí o bá jẹ ya ara rẹ lọ́mú.

Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

35 Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun ní, “Nítorí pé o ti gbàgbé mi, o sì ti kọ̀ mí sílẹ̀, o óo jìyà ìṣekúṣe ati àgbèrè rẹ.”

Ìdájọ́ Ọlọrun lórí Àwọn Arabinrin Mejeeji

36 OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: “Ìwọ ọmọ eniyan ṣé o óo dá ẹjọ́ Ohola ati Oholiba? Nítorí náà fi ìwà ìríra tí wọ́n hù hàn wọ́n.

37 Nítorí wọ́n ti ṣe àgbèrè, wọ́n sì ti paniyan; wọ́n ṣe àgbèrè ẹ̀sìn lọ́dọ̀ àwọn oriṣa wọn, wọ́n sì ti pa àwọn ọmọ wọn ọkunrin tí wọ́n bí fún mi, bọ oriṣa wọn.

38 Èyí nìkan kọ́ ni wọ́n ṣe sí mi, wọ́n sọ ibi mímọ́ mi di eléèérí, wọ́n sì ba àwọn ọjọ́ ìsinmi mi jẹ́.

39 Ní ọjọ́ náà gan-an tí wọ́n pa àwọn ọmọ wọn, tí wọ́n fi wọ́n rúbọ sí oriṣa wọn, ni wọ́n tún wá sí ilé ìsìn mi, tí wọ́n sọ ọ́ di eléèérí. Wò ó! Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe ní ilé mi.

40 “Wọ́n tilẹ̀ tún ranṣẹ lọ pe àwọn ọkunrin wá láti òkèèrè, oníṣẹ́ ni wọ́n gbé dìde kí ó lọ pè wọ́n wá; àwọn náà sì wá. Nígbà tí wọ́n dé, ẹ wẹ̀, ẹ kun àtíkè, ẹ tọ́ ojú, ẹ sì ṣe ara yín lọ́ṣọ̀ọ́.

41 Ẹ jókòó lórí àga ọlọ́lá. Ẹ tẹ́ tabili siwaju; ẹ wá gbé turari ati òróró mi lé e lórí.

42 Ogunlọ́gọ̀ àwọn aláìbìkítà ẹ̀dá bẹ̀rẹ̀ sí pariwo lọ́dọ̀ yín, àwọn ọkunrin ọ̀mùtí lásánlàsàn kan sì wá láti inú aṣálẹ̀, wọ́n kó ẹ̀gbà sí àwọn obinrin lọ́wọ́, wọ́n fi adé tí ó lẹ́wà dé wọn lórí.

43 Nígbà náà ni mo wí lọ́kàn ara mi pé, Ǹjẹ́ àwọn ọkunrin wọnyi kò tún ń ṣe àgbèrè, pẹlu àwọn obinrin panṣaga burúkú yìí?

44 Nítorí wọ́n ti tọ̀ wọ́n lọ bí àwọn ọkunrin tí ń tọ aṣẹ́wó lọ. Wọ́n wọlé tọ Ohola ati Oholiba lọ, wọ́n sì bá wọn ṣe àgbèrè.

45 Ṣugbọn àwọn olódodo eniyan ni yóo dá àwọn obinrin náà lẹ́jọ́ panṣaga, ati ti apànìyàn, nítorí pé panṣaga eniyan ni wọ́n, wọ́n sì ti paniyan.”

46 Nítorí pé OLUWA Ọlọrun ní, “Ẹ pe ogunlọ́gọ̀ eniyan lé wọn lórí kí wọ́n ṣẹ̀rù bà wọ́n, kí wọ́n sì kó wọn lẹ́rù;

47 kí ogunlọ́gọ̀ eniyan wọnyi óo sọ wọ́n lókùúta, wọn óo sì gún wọn ní idà. Wọn óo pa àwọn ọmọ wọn; tọkunrin tobinrin, wọn óo sì dáná sun ilé wọn.

48 Bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe fi òpin sí ìṣekúṣe ní ilẹ̀ náà; èyí óo sì kọ́ gbogbo àwọn obinrin lẹ́kọ̀ọ́, pé kí wọ́n má máa ṣe ìṣekúṣe bíi tiyín.

49 N óo da èrè ìṣekúṣe yín le yín lórí, ẹ óo sì jìyà ẹ̀ṣẹ̀ ìbọ̀rìṣà yín. Ẹ óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA Ọlọrun.”

Categories
ISIKIẸLI

ISIKIẸLI 24

Ìkòkò Ìdáná tí Ó Dípẹtà

1 OLUWA bá mi sọ̀rọ̀ ní ọjọ́ kẹwaa, oṣù kẹwaa, ọdún kẹsan-an tí a ti wà ní ìgbèkùn, ó ní,

2 “Ìwọ ọmọ eniyan, sàmì sí ọjọ́ òní, kọ orúkọ ọjọ́ òní sílẹ̀. Lónìí gan-an ni ọba Babilonia gbógun ti Jerusalẹmu.

3 Pa òwe yìí fún àwọn ọlọ̀tẹ̀ wọnyi kí o sì wí fún wọn pé, ní orúkọ èmi OLUWA Ọlọrun:

Gbé ìkòkò kaná;

bu omi sí i.

4 Kó ègé ẹran sí i,

gbogbo ibi tí ó dára jùlọ lára ẹran,

ẹran itan ati ti èjìká,

kó egungun tí ó dára náà sí i kí ó kún.

5 Ẹran tí ó dára jùlọ ninu agbo ni kí o mú,

kó igi jọ sí abẹ́ ìkòkò náà,

kí o bọ ẹran náà,

bọ̀ ọ́ teegunteegun.”

6 Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun ní: “Ègbé ni fún ìlú apànìyàn, ìkòkò tí inú rẹ̀ dípẹtà, tí ìdọ̀tí rẹ̀ kò ṣí kúrò ninu rẹ̀! Yọ ẹran inú rẹ̀ kúrò lọ́kọ̀ọ̀kan, sá máa mú èyí tí ọwọ́ rẹ bá ti bà.

7 Nítorí pé ẹ̀jẹ̀ eniyan tí ó pa wà ninu rẹ̀, orí àpáta ni ó da ẹ̀jẹ̀ wọn sí, kò dà á sórí ilẹ̀, tí yóo fi rí erùpẹ̀ bò ó.

8 Mo ti da ẹ̀jẹ̀ tí ó ta sílẹ̀ sórí àpáta, kí ó má baà ṣe é bò mọ́lẹ̀. Kí inú lè bí mi, kí n lè gbẹ̀san.”

9 Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun ní: “Ègbé ni fún ìlú tí ó kún fún ìpànìyàn yìí, èmi fúnra mi ni n óo kó iná ńlá jọ.

10 Ẹ kó ọpọlọpọ igi jọ; ẹ ṣáná sí i. Ẹ se ẹran náà dáradára, ẹ da omi rẹ̀ nù, kí ẹ jẹ́ kí egungun rẹ̀ jóná.

11 Lẹ́yìn náà, ẹ gbé òfìfo ìkòkò náà léná, kí ó gbóná, kí idẹ inú rẹ̀ lè yọ́; kí ìdọ̀tí tí ó wà ninu rẹ̀ lè jóná, kí ìpẹtà rẹ̀ sì lè jóná pẹlu.

12 Lásán ni mò ń ṣe wahala, gbogbo ìpẹtà náà kò ní jóná.

13 Jerusalẹmu, ìṣekúṣe ti dípẹtà sinu rẹ, mo fọ̀ ọ́ títí, ìdọ̀tí kò kúrò ninu rẹ, kò sì ní kúrò mọ́ títí n óo fi bínú sí ọ tẹ́rùn.

14 Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀, n óo sì mú un ṣẹ. Bí mo ti wí ni n óo ṣe, n kò ní dáwọ́ dúró, n kò ní dá ẹnikẹ́ni sí, n kò sì ní yí ọkàn pada. Ìwà ati ìṣe yín ni n óo fi da yín lẹ́jọ́. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

Iyawo Wolii Náà Kú

15 OLUWA tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní,

16 “Ìwọ ọmọ eniyan, wò ó! Mo ṣetán tí n óo gba ohun tí ń dùn ọ́ ninu lọ́wọ́ rẹ. Lójijì ni n óo gbà á, o kò sì gbọdọ̀ banújẹ́ tabi kí o sọkún, bẹ́ẹ̀ ni omi kò gbọdọ̀ kán sílẹ̀ lójú rẹ.

17 O lè mí ìmí ẹ̀dùn, ṣugbọn a kò gbọdọ̀ gbọ́ ohùn rẹ, o kò sì gbọdọ̀ ṣọ̀fọ̀. Wé lawani mọ́rí, sì wọ bàtà. O kò gbọdọ̀ fi aṣọ bo ẹnu, o kò sì gbọdọ̀ jẹ oúnjẹ ọlọ́fọ̀.”

18 Mo bá àwọn eniyan sọ̀rọ̀ láàárọ̀, nígbà tí ó di àṣáálẹ́, iyawo mi kú. Nígbà tí ilẹ̀ ọjọ́ keji mọ́, mo ṣe bí OLUWA ti pàṣẹ pé kí n ṣe.

19 Àwọn eniyan bá bi mí pé, “Ṣé kò yẹ kí o sọ ohun tí nǹkan tí ó ń ṣẹlẹ̀ yìí túmọ̀ sí fún wa, tí o fi ń ṣe báyìí.”

20 Mo bá sọ fún wọn pé, “OLUWA ni ó bá mi sọ̀rọ̀,

21 tí ó ní kí n sọ fún ẹ̀yin ọmọ Israẹli pé òun OLUWA sọ pé òun óo sọ ibi mímọ́ òun di aláìmọ́: ibi mímọ́ òun tí ẹ fi ń ṣògo, tí ó jẹ́ agbára yín, tí ẹ fẹ́ràn láti máa wò, tí ọkàn yín sì fẹ́. Ogun yóo pa àwọn ọmọkunrin ati àwọn ọmọbinrin yín tí ẹ fi sílẹ̀.

22 Bí mo ti ṣe yìí gan-an ni ẹ̀yin náà gbọdọ̀ ṣe, ẹ kò gbọdọ̀ fi aṣọ bo ẹnu yín tabi kí ẹ máa jẹ oúnjẹ ọlọ́fọ̀.

23 Lawani yín gbọdọ̀ wà lórí yín; kí bàtà yín sì wà ní ẹsẹ̀ yín, ẹ kò gbọdọ̀ ṣọ̀fọ̀ tabi kí ẹ sọkún. Ẹ óo joró nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yín, ẹ óo sì máa bá ara yín sọ̀rọ̀ tẹ̀dùntẹ̀dùn.

24 Ó ní èmi Isikiẹli óo jẹ́ àmì fun yín, gbogbo bí mo bá ti ṣe ni ẹ̀yin náà gbọdọ̀ ṣe nígbà tí ọ̀rọ̀ yìí bá ṣẹlẹ̀. Ẹ óo sì mọ̀ pé òun ni OLUWA Ọlọrun.”

25 OLUWA ní, “Ìwọ ní tìrẹ, ọmọ eniyan, ní ọjọ́ tí mo bá gba ibi ààbò wọn lọ́wọ́ wọn, àní ayọ̀ ati ògo wọn, ohun tí wọ́n fẹ́ máa rí, tí ọkàn wọn sì fẹ́, pẹlu àwọn ọmọ wọn lọkunrin ati lobinrin,

26 ní ọjọ́ náà, ẹnìkan tí yóo sá àsálà ni yóo wá fún ọ ní ìròyìn.

27 Ní ọjọ́ náà, ẹnu rẹ óo yà, o óo sì le sọ̀rọ̀; o kò ní ya odi mọ́. Ìwọ ni o óo jẹ́ àmì fún wọn; wọn óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA.”

Categories
ISIKIẸLI

ISIKIẸLI 25

Àsọtẹ́lẹ̀ Ibi Nípa Amoni

1 OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní:

2 “Ìwọ ọmọ eniyan, kọjú sí àwọn ará Amoni kí o sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa wọn.

3 Wí fún wọn báyìí pé, ‘Ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA Ọlọrun wí; nítorí pé ẹ̀ ń yọ̀ nígbà tí wọ́n sọ ibi mímọ́ mi di aláìmọ́, ati pé ẹ̀ ń yọ ilẹ̀ Israẹli, nígbà tí wọ́n sọ ọ́ di ahoro, ẹ sì ń yọ ilẹ̀ Juda, nígbà tí wọ́n kó o lọ sí ìgbèkùn;

4 nítorí náà, n óo fà yín lé àwọn ará ilẹ̀ ìlà oòrùn lọ́wọ́, ẹ óo sì di tiwọn. Wọn óo pa àgọ́ sí ààrin yín; wọn óo tẹ̀dó sí ààrin yín; wọn óo máa jẹ èso oko yín, wọn óo sì máa mu wàrà yín.

5 N óo sọ ìlú Raba di pápá àwọn ràkúnmí, àwọn ìlú Amoni yóo sì di pápá ẹran. Wọn óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA!’

6 Nitori báyìí ni OLUWA Ọlọrun wí, “Ẹ̀yin ń pàtẹ́wọ́, ẹ̀ ń fò sókè, ẹ sì ń yọ àwọn ọmọ Israẹli.

7 Nítorí náà, ẹ wò ó! Mo ti nawọ́ ìyà si yín, n óo sì fi yín ṣe ìkógun fún àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn. N óo pa yín run láàrin àwọn eniyan ilẹ̀ ayé, n óo sì pa yín rẹ́ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè, ẹ óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA.”

Àsọtẹ́lẹ̀ Ibi Nípa Moabu

8 OLUWA Ọlọrun ní, “Àwọn ará Moabu ń wí pé ilẹ̀ Juda dàbí àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn,

9 nítorí náà, n óo tú àwọn ìlú Moabu tí wọ́n wà ní apá ọ̀tún ati apá òsì ká: àwọn ìlú tí ó dára jù ní ilẹ̀ Moabu, Beti Jẹṣimoti, Baali Meoni ati Kiriataimu ká.

10 N óo fún àwọn ará ìlà oòrùn ní òun ati ilẹ̀ Amoni, wọn óo di ìkógun, kí á má baà ranti rẹ̀ mọ́ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè.

11 N óo ṣe ìdájọ́ àwọn ará Moabu; wọn yóo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA!”

Àsọtẹ́lẹ̀ Ibi Nípa Edomu

12 OLUWA Ọlọrun ní, “Nítorí àwọn ará Edomu gbẹ̀san lára àwọn ará Juda, wọ́n sì ṣẹ̀ nítorí ẹ̀san tí wọ́n gbà.

13 N óo nawọ́ ìyà sí Edomu, n óo pa ati eniyan ati ẹranko inú rẹ̀ run. N óo sọ ọ́ di ahoro láti Temani títí dé Dedani. Ogun ni yóo pa wọ́n.

14 Àwọn eniyan mi, Israẹli, ni n óo lò láti gbẹ̀san lára Edomu. Bí inú ti bí mi tó, ati bí inú mi ṣe ń ru tó, ni wọn yóo ṣe fi ìyà jẹ Edomu. Wọn óo wá mọ̀ bí mo ti lè gbẹ̀san tó. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

Àsọtẹ́lẹ̀ Ibi Nípa Filistia

15 OLUWA Ọlọrun ní, “Àwọn ará Filistia gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá wọn, wọn sì fi ìkórìíra àtayébáyé pa wọ́n run,

16 nítorí náà, n óo nawọ́ ìyà sí wọn, n óo pa àwọn ọmọ Kereti run, n óo pa àwọn tí ó kù sí etí òkun rẹ́.

17 N óo gbẹ̀san lára wọn lọpọlọpọ; n óo fi ìrúnú fi ìyà ńlá jẹ wọ́n. Wọn óo wá mọ̀ nígbà tí mo bá gbẹ̀san lára wọn pé èmi ni OLUWA.”

Categories
ISIKIẸLI

ISIKIẸLI 26

Àsọtẹ́lẹ̀ Ibi Nípa Tire

1 Ní ọjọ́ kinni oṣù, ní ọdún kọkanla tí a dé ìgbèkùn, OLUWA bá mi sọ̀rọ̀: ó ní,

2 “Ìwọ ọmọ eniyan, nítorí pé àwọn ará ìlú Tire ń yọ̀ sí ìṣubú ìlú Jerusalẹmu, wọ́n ń sọ wí pé ìlẹ̀kùn ibodè àwọn eniyan yìí ti já, ibodè wọn sì ti ṣí sílẹ̀ fún wa, nisinsinyii tí ó di àlàpà, a óo ní àníkún.

3 “Nítorí náà, mo lòdì sí ọ, ìwọ Tire, n óo sì kó ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè wá gbógun tì ọ́, bíi ríru omi òkun.

4 Wọn óo wó odi Tire; wọn óo wó ilé-ìṣọ́ tí ó wà ninu rẹ̀ palẹ̀. N óo ha erùpẹ̀ inú rẹ̀ kúrò, n óo sì sọ ọ́ di àpáta lásán.

5 Yóo di ibi tí wọn óo máa sá àwọ̀n sí láàrin òkun, nítorí èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀; yóo sì di ìkógun fún àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn.

6 Ogun yóo kó àwọn ìlú kéékèèké tí ó wà ní gbogbo agbègbè tí ó yí i ká. Wọn óo wá mọ̀ nígbà náà pé èmi ni OLUWA.”

7 OLUWA Ọlọrun ní, “Ẹ wò ó! N óo mú Nebukadinesari, ọba ńlá Babiloni wá, láti ìhà àríwá, yóo wá gbógun ti Tire. Nebukadinesari, ọba àwọn ọba óo wá, pẹlu ẹṣin ati kẹ̀kẹ́ ogun ati àwọn ẹlẹ́ṣin ati ọpọlọpọ ọmọ ogun.

8 Yóo fi idà pa àwọn ará ìlú kéékèèké tí ó wà ní agbègbè tí ó yí ọ ká. Wọn óo mọ òkítì sí ara odi rẹ, wọn yóo ru erùpẹ̀ jọ, wọn óo fi la ọ̀nà lẹ́yìn odi rẹ, wọn óo sì fi asà borí nígbà tí wọ́n bá ń gun orí odi rẹ bọ̀.

9 Wọn óo fi ìtì igi wó odi rẹ, wọn óo sì fi àáké wó ilé-ìṣọ́ rẹ lulẹ̀.

10 Ẹṣin rẹ̀ óo pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí eruku ẹsẹ̀ wọn yóo bò ọ́ mọ́lẹ̀ nígbà tí wọ́n bá dé ẹnubodè rẹ, ariwo àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀ ati ti àwọn kẹ̀kẹ́ ẹrù ati ti kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ yóo mi odi rẹ tìtì, nígbà tí wọ́n bá dé ẹnubodè rẹ, bí ìgbà tí àwọn ọmọ ogun bá wọ ìlú tí odi rẹ̀ ti wó.

11 Yóo fi pátákò ẹsẹ̀ àwọn ẹṣin rẹ̀ tú gbogbo ilẹ̀ ìgboro rẹ, yóo fi idà pa àwọn eniyan rẹ; yóo sì wó àwọn òpó ńláńlá rẹ lulẹ̀.

12 Yóo kó ọrọ̀ rẹ ati àwọn ọjà tí ò ń tà ní ìkógun. Yóo wó odi rẹ ati àwọn ilé dáradára tí ó wà ninu rẹ lulẹ̀. Yóo ru òkúta, ati igi, ati erùpẹ̀ tí ó wà ninu ìlú rẹ dà sinu òkun.

13 N óo wá fi òpin sí orin kíkọ ninu rẹ; a kò sì ní gbọ́ ohùn dùùrù ninu rẹ mọ́.

14 N óo sì sọ ọ́ di àpáta lásán, o óo di ibi tí wọn óo máa sá àwọ̀n sí; ẹnikẹ́ni kò sì ní tún ọ kọ́ mọ́. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

15 OLUWA Ọlọrun sọ fún ìlú Tire pé, “Ǹjẹ́ gbogbo ilẹ̀ tí ó wà létí òkun kò ní mì tìtì nítorí ìṣubú rẹ, nígbà tí àwọn tí wọ́n farapa bá ń kérora, tí a sì pa ọpọlọpọ ní ìpakúpa ninu rẹ?

16 Gbogbo àwọn ọba ìlú etí òkun yóo sọ̀kalẹ̀ láti orí ìtẹ́ wọn, wọn óo bọ́ aṣọ ìgúnwà wọn, ati agbádá ọlọ́nà tí wọ́n wọ̀, jìnnìjìnnì óo dà bò wọ́n, wọn óo jókòó sórí ilẹ̀, wọn óo bẹ̀rẹ̀ sí máa gbọ̀n, ẹnu óo sì yà wọ́n nítorí ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ sí ọ.

17 Wọn yóo wá dá orin arò fún ọ pé:

Wò ó bí o ti parẹ́ ninu òkun,

ìwọ ìlú olókìkí,

ìwọ ìlú tí ó lágbára lórí òkun,

ìwọ ati àwọn tí ń gbé inú rẹ,

àwọn tí wọn ń mú kí ẹ̀rù rẹ máa ba àwọn tí wọn ń gbé orí ilẹ̀.

18 Àwọn erékùṣù yóo wárìrì ní ọjọ́ ìṣubú rẹ.

Nítòótọ́, àwọn erékùṣù tí wọ́n wà ninu òkun yóo dààmú nítorí ìparun rẹ.”

19 OLUWA Ọlọrun ní, “Nígbà tí mo bá sọ ọ́ di ìlú ìparun bí àwọn ìlú tí ẹnìkan kò gbé inú rẹ̀, nígbà tí mo bá mú kí omi òkun bò ọ́ mọ́lẹ̀, tí ibú omi sì bò ọ́ mọ́lẹ̀,

20 n óo fà ọ́ lulẹ̀ lọ bá àwọn ẹni àtijọ́ tí wọ́n wà ninu ọ̀gbun. N óo mú kí o máa gbé ìsàlẹ̀ ilẹ̀ bí ìlú àwọn tí wọ́n ti ṣègbé nígbà àtijọ́, ati àwọn tí wọ́n ti lọ sinu ọ̀gbun; kí ẹnikẹ́ni má baà gbé inú rẹ mọ́, kí o má sì sí lórí ilẹ̀ alààyè mọ́.

21 N óo mú òpin tí ó bani lẹ́rù dé bá ọ, o kò sì ní sí mọ́; bí ẹnikẹ́ni tilẹ̀ ń wá ọ, ẹnìkan kò ní rí ọ mọ́ títí lae. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

Categories
ISIKIẸLI

ISIKIẸLI 27

Orin Arò fún Ìlú Tire

1 OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní,

2 “Ìwọ ọmọ eniyan, kọ orin arò nípa ìlú Tire.

3 Sọ fún ìlú Tire tí ó wà ní etí òkun, tí ń bá gbogbo àwọn tí wọn ń gbé etí òkun ṣòwò. Sọ fún un pé OLUWA Ọlọrun ní:

Tire, ìwọ tí ò ń sọ pé,

o dára tóbẹ́ẹ̀, tí ẹwà rẹ kò kù síbìkan!

4 Agbami òkun ni bodè rẹ.

Àwọn tí wọ́n kọ́ ọ fi ẹwà jíǹkí rẹ.

5 Igi firi láti Seniri ni wọ́n fi ṣe gbogbo ẹ̀gbẹ́ rẹ.

Igi kedari láti Lẹbanoni ni wọ́n sì fi ṣe òpó ọkọ̀ rẹ.

6 Igi oaku láti Baṣani ni wọ́n fi ṣe ajẹ̀ rẹ̀

Igi sipirẹsi láti erékùṣù Kipru ni wọ́n fi ṣe ilé rẹ.

Wọ́n sì fi eyín erin bo inú rẹ̀.

7 Aṣọ ọ̀gbọ̀ tí wọ́n ṣe iṣẹ́ ọnà sí lára láti ilẹ̀ Ijipti,

ni wọ́n fi ṣe ìgbòkun rẹ

tí ó dàbí àsíá ọkọ̀ rẹ.

Aṣọ aláró ati aṣọ àlàárì láti etíkun Eliṣa

ni wọ́n fi ṣe ìbòrí rẹ.

8 Àwọn ará Sidoni ati Arifadi ni atukọ̀ rẹ.

Àwọn ọlọ́gbọ́n láti ilẹ̀ Ṣemeri wà lọ́dọ̀ rẹ,

àwọn ni wọ́n ń darí ọkọ̀ ojú omi rẹ.

9 Àwọn àgbààgbà Gebali ati àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n oníṣẹ́ ọwọ́ wà lọ́dọ̀ rẹ,

àwọn ni wọ́n ń fi ọ̀dà dí ọkọ̀ rẹ

kí omi má baà wọnú rẹ̀.

Gbogbo ọkọ̀ ojú omi ati àwọn tí ń tù wọ́n

wà lọ́dọ̀ rẹ, wọ́n ń bá ọ ra ọjà.

10 “Àwọn ará Pasia ati àwọn ará Ludi ati àwọn ará Puti wà láàrin àwọn ọmọ ogun rẹ bí akọni. Wọ́n gbé asà ati àṣíborí wọn kọ́ sinu rẹ, wọ́n jẹ́ kí o gba ògo.

11 Àwọn ará Arifadi ati Heleki wà lórí odi rẹ yíká, àwọn ará Gamadi sì wà ninu àwọn ilé-ìṣọ́ rẹ. Wọ́n gbé asà wọn kọ́ káàkiri ara ògiri rẹ, àwọn ni wọ́n mú kí ẹwà rẹ pé.

12 “Àwọn ará Taṣiṣi ń bá ọ rajà nítorí ọpọlọpọ ọrọ̀ rẹ: fadaka, irin, páànù ati òjé ni wọ́n fi ń ṣe pàṣípààrọ̀ ọjà lọ́dọ̀ rẹ.

13 Àwọn ará Jafani, Tubali, ati Meṣeki ń bá ọ ṣòwò; wọ́n ń kó ẹrú ati ohun èlò idẹ wá fún ọ, wọn fi ń gba àwọn nǹkan tí ò ń tà.

14 Àwọn ará Beti Togama a máa kó ẹṣin, ati ẹṣin ogun, ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wá ṣe pàṣípààrọ̀ àwọn nǹkan tí ò ń tà.

15 Àwọn ará Didani ń bá ọ ṣòwò, ọpọlọpọ etíkun ni ẹ tí ń tajà, wọ́n ń fi eyín erin ati igi Ẹboni ṣe pàṣípààrọ̀ fún ọ.

16 Àwọn ará Edomu bá ọ ṣòwò nítorí ọpọlọpọ ọjà tí ò ń tà. Òkúta emeradi, aṣọ àlàárì, aṣọ funfun onílà tẹ́ẹ́rẹ́ tẹ́ẹ́rẹ́, iyùn ati òkúta agate ni wọ́n fi ń ṣe pàṣípààrọ̀ fún ọ.

17 Juda ati ilé Israẹli bá ọ ṣòwò: wọ́n ń kó ọkà, èso olifi, àkọ́so èso ọ̀pọ̀tọ́, oyin, òróró ati òrí wá láti fi ṣe pàṣípààrọ̀ àwọn nǹkan tí ò ń tà.

18 Àwọn ará Damasku bá ọ ṣòwò nítorí ọpọlọpọ ọjà ati àwọn nǹkan olówó iyebíye tí ò ń tà, wọ́n mú ọtí waini ati irun aguntan funfun wá láti Heliboni.

19 Àwọn ará Fedani ati Jafani láti Usali a máa wá fi ọtí waini pààrọ̀ ohun tí ò ń tà; wọn a kó àwọn nǹkan èlò irin wá, ati igi kasia.

20 Àwọn ará Dedani náà ń bá ọ ṣòwò, wọ́n ń kó aṣọ gàárì tí wọ́n fi ń gun ẹṣin wá.

21 Àwọn ará Arabia ati àwọn olóyè Kedari ni àwọn oníbàárà rẹ pataki, wọn a máa ra ọ̀dọ́ aguntan, àgbò, ati ewúrẹ́ lọ́wọ́ rẹ.

22 Àwọn oníṣòwò Ṣeba ati ti Raama náà a máa bá ọ ra ọjà, oríṣìíríṣìí turari olóòórùn dídùn ati òkúta olówó iyebíye ati wúrà ni wọ́n fi ń ṣe pàṣípààrọ̀ ọjà lọ́wọ́ rẹ.

23 Àwọn ará Harani, Kane, Edẹni, Aṣuri ati Kilimadi ń bá ọ ṣòwò.

24 Wọ́n ń kó ojúlówó ẹ̀wù aṣọ aláwọ̀ aró wá tà fún ọ, ati aṣọ tí wọ́n ṣe iṣẹ́ ọnà sí lára, ati ẹni tí ó ní oríṣìíríṣìí àwọ̀, tí wọ́n fi ìko hun.

25 Àwọn ọkọ̀ Taṣiṣi ní ń bá ọ ru ọjà rẹ lọ ta.

Ọjà kún inú rẹ,

ẹrù rìn ọ́ mọ́lẹ̀ láàrin omi òkun.

26 Àwọn tí ń wà ọ́ ti tì ọ́ sí ààrin agbami òkun.

Atẹ́gùn ńlá ti dà ọ́ nù láàrin agbami òkun.

27 Gbogbo ọrọ̀ rẹ, ati gbogbo ọjà olówó iyebíye rẹ,

àwọn tí ń tu ọkọ̀ rẹ ati àwọn tí ń darí rẹ;

àwọn tí ń fi ọ̀dà dí ihò ara ọkọ̀ rẹ

ati àwọn tí ń bá ọ ṣòwò.

Gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ ati àwọn èrò tí ó wà ninu rẹ,

ni yóo rì sí ààrin gbùngbùn òkun, ní ọjọ́ ìparun rẹ.

28 Gbogbo èbúté yóo mì tìtì

nígbà tí àwọn tí wọn ń tọ́ ọkọ̀ rẹ bá kígbe.

29 Gbogbo àwọn atukọ̀ ni yóo jáde kúrò ninu ọkọ̀.

Àwọn tí ń ṣiṣẹ́ ninu ọkọ̀

ati àwọn tí ń darí ọkọ̀

yóo dúró ní èbúté.

30 Wọn óo gbé ohùn sókè sí ọ,

wọn óo sun ẹkún kíkan kíkan.

Wọn óo da erùpẹ̀ sórí wọn,

wọn óo yíra mọ́lẹ̀ ninu eérú.

31 Wọn óo fá irun orí wọn nítorí rẹ,

wọn óo sán aṣọ ọ̀fọ̀ mọ́ ìdí,

wọn óo sì fi ìbànújẹ́ ọkàn sọkún nítorí rẹ,

inú wọn yóo sì bàjẹ́.

32 Bí wọ́n bá ti ń sọkún,

wọn óo máa kọ orin arò nípa rẹ báyìí pé:

‘Ìlú wo ló tíì parun bíi Tire, láàrin òkun?

33 Nígbà tí àwọn ọjà rẹ bá dé láti òkè òkun,

ò ń tẹ́ ọpọlọpọ eniyan lọ́rùn.

Ò ń fi ọpọlọpọ ọrọ̀ rẹ ati ọjà rẹ

sọ àwọn ọba ayé di ọlọ́rọ̀.

34 Wàyí ò, omi òkun ti fọ́ ọ sí wẹ́wẹ́,

o ti rì sí ìsàlẹ̀ òkun.’

Gbogbo àwọn ọjà rẹ

ati àwọn tí ń wa ọkọ̀ rẹ ti rì pẹlu rẹ.

35 “Ẹnu ya gbogbo àwọn tí ń gbé etí òkun nítorí ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí ọ. Àwọn ọba wọn ń gbọ̀n jìnnìjìnnì, ẹ̀rù sì hàn ní ojú wọn.

36 Àwọn oníṣòwò orílẹ̀-èdè ayé ń pòṣé lé ọ lórí. Òpin burúkú dé bá ọ, o kò ní sí mọ́ títí lae.”

Categories
ISIKIẸLI

ISIKIẸLI 28

Àsọtẹ́lẹ̀ Ibi Nípa Ọba Tire

1 OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní,

2 “Ìwọ ọmọ eniyan, sọ fún ọba Tire pé OLUWA ní, ‘Nítorí pé ìgbéraga kún ọkàn rẹ, o sì ti sọ ara rẹ di oriṣa, o sọ pé o jókòó ní ibùjókòó àwọn oriṣa láàrin òkun; bẹ́ẹ̀ sì ni eniyan ni ọ́, o kì í ṣe oriṣa. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ò ń rò pé o gbọ́n bí àwọn oriṣa,

3 nítòótọ́, o gbọ́n ju Daniẹli lọ, kò sì sí ohun àṣírí kan tí ó ṣú ọ lójú.

4 Nípa ọgbọ́n ati ìmọ̀ rẹ, o ti kó ọpọlọpọ ọrọ̀ jọ fún ara rẹ, o sì kó wúrà ati fadaka jọ sinu ilé ìṣúra rẹ.

5 O ti ní àníkún ọrọ̀ nítorí ọgbọ́n rẹ ninu òwò ṣíṣe, ìgbéraga sì ti kún ọkàn rẹ nítorí ọrọ̀ rẹ.’

6 “Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun ní, ‘Nítorí pé o ka ara rẹ kún ọlọ́gbọ́n bí àwọn oriṣa,

7 n óo kó àwọn àjèjì wá bá ọ; àwọn tí wọ́n burú jù ninu àwọn orílẹ̀-èdè, wọn óo sì gbógun tì ọ́, wọ́n yóo sì ba ẹwà ati ògo rẹ jẹ́, pẹlu ọgbọ́n rẹ.

8 Wọn óo tì ọ́ sinu ọ̀gbun; o óo sì kú ikú ogun láàrin omi òkun.

9 Ṣé o óo lè sọ pé oriṣa kan ni ọ́ lójú àwọn tí wọ́n bá fẹ́ pa ọ́? Nígbà tí wọ́n bá ń ṣá ọ lọ́gbẹ́, ṣé eniyan ni o óo wá pe ara rẹ àbí oriṣa.

10 Ikú aláìkọlà ni o óo kú lọ́wọ́ àwọn àjèjì, nítorí èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.’ ”

Ìṣubú Ọba Tire

11 OLUWA tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní,

12 “Ìwọ ọmọ eniyan, kọ orin arò nítorí ohun tí ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ sí ọba Tire. Wí fún un pé OLUWA Ọlọrun ní: ‘O ti jẹ́ àpẹẹrẹ ìwà pípé, o kún fún ọgbọ́n, o sì lẹ́wà tóbẹ́ẹ̀ tí o kò ní àbùkù kankan.

13 O wà ninu Edẹni, ọgbà Ọlọrun. Gbogbo òkúta olówó iyebíye ni wọ́n fi ṣe ọ́ lọ́ṣọ̀ọ́, àwọn òkúta bíi: kaneliani, topasi, ati jasiperi; kirisolite, bẹrili, ati onikisi; safire, kabọnku ati emeradi. A gbé ọ ka inú àwọn nǹkan ọ̀ṣọ́ wúrà tí a ṣe fún ọ ní ọjọ́ tí a dá ọ.

14 Mo fi kerubu tí a fi àmì òróró yàn tì ọ́. O wà lórí òkè mímọ́ èmi Ọlọrun, o sì ń rìn láàrin àwọn òkúta olówó iyebíye tí ń tàn yinrinyinrin.

15 O péye ninu gbogbo ọ̀nà rẹ, láti ọjọ́ tí wọ́n ti dá ọ títí di ìgbà tí a rí ẹ̀ṣẹ̀ lọ́wọ́ rẹ.

16 Ninu ọpọlọpọ òwò tí ó ń ṣe, o bẹ̀rẹ̀ sí hu ìwà jàgídíjàgan, o sì dẹ́ṣẹ̀, nítorí náà mo lé ọ jáde bí ohun ìríra kúrò lórí òkè Ọlọrun. Kerubu tí ń ṣọ́ ọ sì lé ọ jáde kúrò láàrin àwọn òkúta olówó iyebíye tí ń tàn yinrinyinrin.

17 Ọkàn rẹ kún fún ìgbéraga nítorí pé o lẹ́wà, o ba ọgbọ́n rẹ jẹ́ nítorí ògo rẹ. Mo bì ọ́ lulẹ̀, mo sọ ọ́ di ìran wíwò fún àwọn ọba.

18 O ti fi ọpọlọpọ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ tí o dá nítorí ìwà aiṣootọ ninu òwò rẹ, ba ibi mímọ́ mi jẹ́. Nítorí náà, mo jẹ́ kí iná ṣẹ́ ní ààrin rẹ; ó sì jó ọ run; mo sì sọ ọ́ di eérú lórí ilẹ̀ ayé lójú gbogbo àwọn tí ń wò ọ́.

19 Gbogbo àwọn tí wọ́n mọ̀ ọ́ láàrin àwọn eniyan láyé ni ó yà lẹ́nu nígbà tí wọ́n rí ọ. Òpin burúkú ti dé bá ọ, o kò sì ní sí mọ́ títí ayé.’ ”

Àsọtẹ́lẹ̀ Ibi Nípa Sidoni

20 OLUWA tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní,

21 “Ìwọ ọmọ eniyan, kọjú rẹ sí Sidoni, kí o sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀ pé

22 OLUWA Ọlọrun ní, ‘Wò ó, mo lòdì sí ọ, ìwọ Sidoni. N óo sì fi ògo mi hàn láàrin rẹ. Wọn óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA nígbà tí mo bá ṣe ìdájọ́ fún àwọn tí ń gbé inú rẹ; tí mo sì fi ìwà mímọ́ mi hàn wọ́n.

23 Nítorí n óo fi àjàkálẹ̀ àrùn bá ọ jà n óo sì jẹ́ kí àgbàrá ẹ̀jẹ̀ máa ṣàn ní ìgboro rẹ. Àwọn tí wọ́n yí ọ ká yóo gbógun tì ọ́, wọn óo sì fi idà pa ọpọlọpọ eniyan ninu rẹ,’ nígbà náà o óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA.”

A óo Bukun Israẹli

24 OLUWA Ọlọrun ní, “Ní ti ilé Israẹli, kò ní sí ọ̀tá tí yóo máa ṣe ẹ̀gún gún wọn mọ́, láàrin gbogbo àwọn tí wọ́n yí wọn ká tí wọ́n sì ń kẹ́gàn wọn. Wọn óo wá mọ̀ nígbà náà pé èmi ni OLUWA.

25 “Nígbà tí mo bá kó àwọn ará ilé Israẹli jọ kúrò láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tí mo fọ́n wọn ká sí, tí mo sì fi ìwà mímọ́ mi hàn láàrin wọn, lójú àwọn orílẹ̀-èdè yòókù, wọn óo máa gbé ilẹ̀ tiwọn, ilẹ̀ tí mo fún Jakọbu iranṣẹ mi.

26 Wọn óo máa gbé ibẹ̀ láìbẹ̀rù; wọn óo kọ́ ilé, wọn óo sì ṣe ọgbà àjàrà, wọn óo máa gbé láìbẹ̀rù nígbà tí mo bá ṣe ìdájọ́ gbogbo àwọn tí wọ́n yí wọn ká, tí wọ́n sì ti kẹ́gàn wọn. Wọn óo wá mọ̀ nígbà náà pé èmi ni OLUWA Ọlọrun wọn.”

Categories
ISIKIẸLI

ISIKIẸLI 29

Àsọtẹ́lẹ̀ Ibi Nípa Ijipti

1 Ní ọjọ́ kejila oṣù kẹwaa ọdún kẹwaa, OLUWA bá mi sọ̀rọ̀;

2 Ó ní, “Ìwọ ọmọ eniyan, kọjú rẹ sí Farao ọba Ijipti, kí o sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa òun ati gbogbo àwọn ará Ijipti pé,

3 OLUWA Ọlọrun ní: Wò ó, mo lòdì sí ọ, ìwọ Farao, ọba Ijipti, Ìwọ diragoni ńlá tí o wà láàrin odò rẹ; tí o wí pé, ‘Èmi ni mo ni odò Naili mi; ara mi ni mo dá a fún.’

4 N óo fi ìwọ̀ kọ́ ọ lẹ́nu, n óo sì jẹ́ kí àwọn ẹja inú odò Naili so mọ́ ìpẹ́ rẹ; n óo sì fà ọ́ jáde kúrò ninu odò Naili rẹ pẹlu gbogbo àwọn ẹja inú odò rẹ tí wọn óo so mọ́ ọ lára.

5 N óo gbé ọ jù sinu aṣálẹ̀, ìwọ ati gbogbo ẹja inú odò Naili rẹ. Ẹ ó bọ́ lulẹ̀ ninu pápá tí ó tẹ́jú. Ẹnìkan kò sì ní kó òkú yín jọ, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní sin yín. Mo ti fi yín ṣe oúnjẹ fún àwọn ẹranko ati àwọn ẹyẹ.

6 Gbogbo àwọn tí wọn ń gbé Ijipti yóo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA.

“Nítorí pé ẹ fi ara yín ṣe ọ̀pá tí àwọn ọmọ Israẹli gbára lé; ṣugbọn ọ̀pá tí kò gbani dúró ni yín.

7 Nígbà tí wọ́n gba yín mú, dídá ni ẹ dá mọ́ wọn lọ́wọ́, tí ẹ ya wọ́n léjìká pẹ́rẹpẹ̀rẹ. Nígbà tí wọ́n gbára le yín, ẹ dá ẹ sì jẹ́ kí wọ́n dá lẹ́yìn.”

8 Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun ní: “Wò ó, n óo fi ogun jà yín, n óo sì pa yín run, ati eniyan ati ẹranko.

9 Ilẹ̀ Ijipti yóo di ahoro, yóo sì di aṣálẹ̀. Wọn yóo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA.

“Nítorí o wí pé, ‘Èmi ni mo ni odò Naili, ara mi ni mo dá a fún,’

10 nítorí náà, mo lòdì sí ìwọ ati àwọn odò rẹ, n óo sì sọ ilẹ̀ Ijipti di ahoro ati aṣálẹ̀ patapata láti Migidoli dé Siene, títí dé ààlà Etiopia.

11 Eniyan tabi ẹranko kò ní gba ibẹ̀ kọjá, ẹnikẹ́ni kò ní gbé ibẹ̀ fún ogoji ọdún.

12 N óo sọ ilẹ̀ Ijipti di ahoro patapata, n óo jẹ́ kí àwọn ìlú rẹ̀ di ahoro fún ogoji ọdún. N óo fọ́n àwọn ará Ijipti káàkiri gbogbo ayé, n óo sì tú wọn ká sí ààrin àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn.”

13 OLUWA Ọlọrun ní, “Lẹ́yìn ogoji ọdún, n óo kó àwọn ará Ijipti jọ láti gbogbo orílẹ̀-èdè tí mo bá fọ́n wọn ká sí.

14 N óo dá ire wọn pada, n óo kó wọn pada sí ilẹ̀ Patirosi, níbi tí a bí wọn sí. Wọn óo sì wà níbẹ̀ bí ìjọba tí kò lágbára.

15 Òun ni yóo rẹlẹ̀ jù láàrin àwọn orílẹ̀-èdè, kò ní lè gbé ara rẹ̀ ga láàrin àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn mọ́. N óo sọ wọ́n di kékeré tóbẹ́ẹ̀ tí wọn kò ní lè jọba lórí orílẹ̀-èdè kankan mọ́.

16 Ijipti kò ní tó gbójú lé fún àwọn ọmọ Israẹli mọ́. Ijipti yóo máa rán wọn létí ẹ̀ṣẹ̀ wọn, pé wọ́n ti wá bèèrè ìrànlọ́wọ́ lọ́dọ̀ àwọn ará Ijipti tẹ́lẹ̀ rí. Wọn óo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA Ọlọrun.”

Nebukadinesari Yóo Ṣẹgun Ijipti

17 Ní ọjọ́ kinni, oṣù kinni, ọdún kẹtadinlọgbọn, OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní,

18 “Ìwọ ọmọ eniyan, Nebukadinesari ọba Babiloni mú àwọn ọmọ ogun rẹ̀ gbógun ti ìlú Tire kíkankíkan. Wọ́n ru ẹrù títí orí gbogbo wọn pá, èjìká gbogbo wọn sì di egbò. Sibẹ òun ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ kò rí èrè kankan gbà ninu gbogbo wahala tí wọ́n ṣe ní Tire.

19 Nítorí náà, èmi OLUWA Ọlọrun óo fi ilẹ̀ Ijipti lé Nebukadinesari, ọba Babiloni lọ́wọ́. Yóo kó àwọn eniyan rẹ̀ lọ, yóo sì fi ọrọ̀ ilẹ̀ Ijipti ṣe ìkógun, èyí ni yóo jẹ́ èrè fún àwọn ọmọ ogun rẹ̀.

20 Mo ti fún un ní ilẹ̀ Ijipti gẹ́gẹ́ bí èrè gbogbo wahala rẹ̀, nítorí pé èmi ni ó ṣiṣẹ́ fún. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

21 “Ní ọjọ́ náà, n óo gbé alágbára kan dìde ní Israẹli, n óo mú kí ìwọ Isikiẹli ó sọ̀rọ̀ láàrin wọn. Nígbà náà, wọn yóo mọ̀ pé èmi ni OLUWA.”