Categories
ISIKIẸLI

ISIKIẸLI 10

Ògo OLUWA Kúrò Ninu Tẹmpili Náà

1 Lẹ́yìn náà, mo wo orí àwọn Kerubu, mo rí kinní kan róbótó róbótó, wọ́n dàbí òkúta safire, ìrísí wọn dàbí ìtẹ́.

2 Ọlọrun bá sọ fún ọkunrin tí ó wọ aṣọ funfun náà pé, “Bọ́ sí ààrin àwọn àgbá tí wọn ń yí, tí wọ́n wà lábẹ́ àwọn Kerubu. Bu ẹ̀yinná tí ó wà láàrin wọn kún ọwọ́ rẹ, kí o sì fọ́n ọn sórí ìlú yìí káàkiri.”

Mo bá rí i tí ó wọlé lọ.

3 Ìhà gúsù ilé náà ni àwọn Kerubu dúró sí nígbà tí ọkunrin náà wọlé, ìkùukùu sì bo àgbàlá ààrin ilé náà.

4 Ìfarahàn ògo OLUWA gbéra kúrò lórí àwọn Kerubu, ó lọ dúró sí àbáwọlé. Ìkùukùu kún gbogbo inú ilé náà, ìmọ́lẹ̀ ògo OLUWA sì kún gbogbo inú àgbàlá.

5 Ariwo ìyẹ́ àwọn Kerubu náà dé àgbàlá òde. Ó dàbí ìgbà tí Ọlọrun Olodumare bá ń sọ̀rọ̀.

6 Nígbà tí OLUWA pàṣẹ fún ọkunrin tí ó wọ aṣọ funfun náà pé kí ó mú iná láàrin àwọn àgbá tí ń yí, tí ó wà láàrin àwọn Kerubu, ọkunrin náà wọlé, ó lọ dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ àgbá náà.

7 Ọ̀kan lára àwọn Kerubu náà na ọwọ́ sí inú iná tí ó wà láàrin wọn, ó bù ú sí ọwọ́ ọkunrin aláṣọ funfun náà. Ọkunrin náà gbà á, ó sì jáde.

8 Ó dàbí ẹni pé àwọn Kerubu náà ní ọwọ́ bíi ti eniyan lábẹ́ ìyẹ́ wọn.

9 Mo wòye, mo sì rí i pé àgbá mẹrin ni ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn Kerubu náà: àgbá kọ̀ọ̀kan wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Kerubu kọ̀ọ̀kan. Àwọn kẹ̀kẹ́ náà ń dán yinrinyinrin bí òkúta Kirisolite.

10 Àwọn mẹrẹẹrin rí bákan náà, ó sì dàbí ìgbà tí àwọn àgbá náà wọnú ara wọn.

11 Bí wọn tí ń lọ, ibikíbi tí ó bá wu àwọn Kerubu náà ninu ẹ̀gbẹ́ mẹrẹẹrin tí wọ́n kọjú sí ni wọ́n lè lọ láì jẹ́ pé wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ yí ojú pada, nítorí pé ibikíbi tí èyí tí ó wà níwájú bá kọjú sí ni àwọn yòókù máa ń lọ.

12 Gbogbo ara wọn àtẹ̀yìn wọn, àtọwọ́, àtìyẹ́ ati gbogbo ẹ̀gbẹ́ kẹ̀kẹ́ wọn kún fún ojú.

13 Mo gbọ́ tí wọ́n pe àwọn àgbá náà ní àgbá tí ń sáré yí.

14 Ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu wọn ní iwájú mẹrin mẹrin. Iwájú kinni jẹ́ iwájú Kerubu, ekeji jẹ́ iwájú eniyan, ẹkẹta jẹ́ iwájú kinniun, ẹkẹrin sì jẹ́ iwájú ẹyẹ idì.

15 Àwọn Kerubu náà bá gbéra nílẹ̀, àwọn ni ẹ̀dá alààyè tí mo rí ní etí odò Kebari.

16 Bí wọn tí ń lọ, bẹ́ẹ̀ ni àwọn àgbá náà ń lọ lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn. Bí àwọn Kerubu náà bá fẹ́ fò, tí wọ́n bá na ìyẹ́ apá wọn, àwọn àgbá náà kìí kúrò lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn.

17 Bí wọn bá dúró, àwọn náà á dúró. Bí wọn bá gbéra nílẹ̀, àwọn náà á gbéra, nítorí pé ẹ̀mí àwọn ẹ̀dá alààyè náà wà ninu wọn.

18 Ìtànṣán ògo OLUWA jáde kúrò ní àbáwọlé, ó sì dúró sí orí àwọn Kerubu náà.

19 Àwọn Kerubu bá na ìyẹ́ apá wọn, wọ́n gbéra nílẹ̀ lójú mi, bí wọ́n ti ń lọ, àwọn àgbá náà wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn. Wọ́n dúró lẹ́nu ọ̀nà ilé OLUWA tí ó kọjú sí ìhà ìlà oòrùn, ìtànṣán ògo Ọlọrun Israẹli sì wà lórí wọn.

20 Àwọn wọnyi ni àwọn ẹ̀dá alààyè tí mo rí lábẹ́ Ọlọrun Israẹli ní etí odò Kebari. Mo sì mọ̀ pé Kerubu ni wọ́n.

21 Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní iwájú mẹrin mẹrin ati ìyẹ́ mẹrin mẹrin, wọ́n sì ní ọwọ́ bí ọwọ́ eniyan lábẹ́ ìyẹ́ wọn.

22 Bí iwájú àwọn tí mo rí lẹ́bàá odò Kebari ti rí gan-an ni iwájú wọn rí. Olukuluku ń rìn lọ siwaju tààrà.

Categories
ISIKIẸLI

ISIKIẸLI 11

(OLUWA Bá Jerusalẹmu Wí)

1 Ẹ̀mí gbé mi lọ sí ẹnu ọ̀nà ilé OLUWA tí ó kọjú sí ìhà ìlà oòrùn. Àwọn ọkunrin mẹẹdọgbọn kan wà lẹ́nu ọ̀nà náà, mo rí i pé àwọn meji láàrin wọn jẹ́ ìjòyè: Jaasanaya, ọmọ Aṣuri, ati Pelataya, ọmọ Bẹnaya.

2 OLUWA sọ fún mi, pé, “Ìwọ Ọmọ eniyan, àwọn tí wọn ń gbèrò ibi nìyí; tí wọn ń fún àwọn eniyan ìlú yìí ní ìmọ̀ràn burúkú.

3 Wọ́n ń wí pé, ‘àkókò ilé kíkọ́ kò tíì tó. Ìlú yìí dàbí ìkòkò,àwa sì dàbí ẹran.’

4 Nítorí náà, sọ àsọtẹ́lẹ̀ burúkú nípa wọn, ìwọ ọmọ eniyan, sọ àsọtẹ́lẹ̀.”

5 Ẹ̀mí OLUWA bá bà lé mi, ó sọ fún mi, pé, “OLUWA ní, Èrò yín nìyí, ẹ̀yin ọmọ Israẹli, mo mọ ohun tí ẹ̀ ń rò lọ́kàn,

6 Ẹ ti pa ọpọlọpọ eniyan ní ààrin ìlú yìí; ẹ sì ti da òkú wọn kún gbogbo ìgboro ati òpópónà ìlú.

7 “Nítorí náà, àwọn òkú yín tí ẹ dà sí ààrin ìlú yìí ni ẹran, ìlú yìí sì ni ìkòkò, ṣugbọn n óo mu yín kúrò láàrin rẹ̀.

8 Idà ni ẹ̀ ń bẹ̀rù, idà náà ni n óo sì jẹ́ kí ó pa yín. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo wí bẹ́ẹ̀.

9 N óo ko yín kúrò ninu ìlú yìí, n óo sì ko yín lé àwọn àjèjì lọ́wọ́. N óo sì ṣe ìdájọ́ yín.

10 Idà yóo pa yín, ààlà ilẹ̀ Israẹli ni n óo ti ṣe ìdájọ́ yín; ẹ óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA.

11 Ìlú yìí kò ní jẹ́ ìkòkò fun yín, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò ní jẹ́ ẹran ninu rẹ̀; ní ààlà ilẹ̀ Israẹli ni n óo ti ṣe ìdájọ́ yín.

12 Ẹ óo mọ̀ pé èmi ni OLUWA; nítorí pé ẹ kò rìn ninu ìlànà mi, ẹ kò sì pa òfin mi mọ́, ṣugbọn ẹ ti gba àṣà àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n yi yín ká.”

13 Bí mo tí ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ lọ́wọ́ ni Pelataya, ọmọ Bẹnaya, bá kú. Mo bá dojúbolẹ̀, mo kígbe sókè, mo ní, “Áà! OLUWA Ọlọrun, ṣé o fẹ́ pa àwọn ọmọ Israẹli yòókù tán ni?”

Ìlérí Ọlọrun sí Àwọn tí Wọ́n Wà Ní Ìgbèkùn

14 OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní:

15 “Ìwọ ọmọ eniyan, gbogbo àwọn tí wọn ń gbé Jerusalẹmu, ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn arakunrin wọn, tí ẹ jọ wà ní ìgbèkùn, àní gbogbo ilé Israẹli; wọ́n ń sọ pé, ‘Wọ́n ti lọ jìnnà kúrò lọ́dọ̀ OLUWA, OLUWA sì ti fún wa ní ilẹ̀ yìí gẹ́gẹ́ bí ohun ìní.’

16 “Nítorí náà wí fún wọn pé èmi, OLUWA Ọlọrun ní, bí mo tilẹ̀ kó wọn lọ jìnnà sí ààrin àwọn orílẹ̀-èdè, tí mo sì fọ́n wọn káàkiri ilẹ̀ ayé, sibẹsibẹ mo jẹ́ ibi mímọ́ fún wọn fún ìgbà díẹ̀ ní ilẹ̀ tí wọ́n lọ.

17 “Nítorí náà, wí fún wọn pé èmi, ‘OLUWA Ọlọrun ní n óo kó wọn jọ láti ààrin àwọn ẹ̀yà ati orílẹ̀-èdè mìíràn tí mo fọ́n wọn ká sí, n óo sì fún wọn ní ilẹ̀ Israẹli.’

18 Nígbà tí wọ́n bá dé ibẹ̀, wọn óo ṣa gbogbo ohun ẹ̀gbin ati ìríra rẹ̀ kúrò ninu rẹ̀.

19 Ó ní, mo sọ pé, n óo fún wọn ní ọkàn kan, n óo fi ẹ̀mí titun sí wọn ninu. N óo yọ ọkàn òkúta kúrò láyà wọn, n óo sì fún wọn ní ọkàn ẹran;

20 kí wọ́n lè máa rìn ninu ìlànà mi, kí wọ́n sì lè máa pa òfin mi mọ́. Wọn óo jẹ́ eniyan mi, èmi náà óo sì jẹ́ Ọlọrun wọn.

21 Ṣugbọn n óo fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ jẹ àwọn tí ọkàn wọn ń fà sí àwọn ohun ẹ̀gbin ati ìríra. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

Ògo OLUWA Kúrò ní Jerusalẹmu

22 Lẹ́yìn náà, àwọn Kerubu bá gbéra, wọ́n fò, pẹlu àgbá, ní ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ wọn; ìtànṣán ògo OLUWA Ọlọrun Israẹli sì wà lórí wọn.

23 Ògo OLUWA gbéra kúrò láàrin ìlú náà, ó sì dúró sórí òkè tí ó wà ní apá ìhà ìlà oòrùn ìlú náà.

24 Ẹ̀mí bá gbé mi sókè ní ojúran, ó gbé mi wá sí ilẹ̀ àwọn ará Kalidea, lọ́dọ̀ àwọn tí wọ́n wà ní ìgbèkùn. Lẹ́yìn náà, ìran tí mo rí bá kúrò lójú mi.

25 Mo sì sọ gbogbo ohun tí OLUWA fihàn mí fún àwọn tí wọ́n wà ní ìgbèkùn.

Categories
ISIKIẸLI

ISIKIẸLI 12

Wolii Gẹ́gẹ́ Bí Ẹni Tí Ó sá fógun

1 OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní:

2 “Ìwọ ọmọ eniyan, ààrin àwọn olóríkunkun ni o wà: àwọn tí wọ́n ní ojú, ṣugbọn tí wọn kò fi ríran. Wọ́n ní etí, ṣugbọn wọn kò fi gbọ́ràn, nítorí pé ọmọ ọlọ̀tẹ̀ ni wọ́n.

3 “Nítorí náà, ìwọ ọmọ eniyan, di ẹrù rẹ bíi ti ẹni tí ń lọ sí ìgbèkùn, kí o sì jáde ní ìlú lọ́sàn-án gangan níṣojú wọn. Lọ láti ilé rẹ sí ibòmíràn bí ẹni tí ń lọ sí ìgbèkùn. Bóyá yóo yé wọn bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọ ọlọ̀tẹ̀ ni wọ́n.

4 Kó ẹrù rẹ jáde lójú wọn ní ọ̀sán gangan kí ìwọ pàápàá jáde lójú wọn ní ìrọ̀lẹ́ bí ẹni tí ń lọ sí ìgbèkùn.

5 Dá odi ìlú lu níṣojú wọn, kí o sì gba ibẹ̀ jáde.

6 Gbé ẹrù rẹ lé èjìká níṣojú wọn, kí o sì jáde ní òru. Fi nǹkan bojú rẹ kí o má baà rí ilẹ̀, nítorí pé ìwọ ni mo ti fi ṣe àmì fún ilé Israẹli.”

7 Mo ṣe bí OLUWA ti pàṣẹ fún mi. Mo gbé ẹrù mi jáde lọ́sàn-án gangan bí ẹrù ẹni tí ń lọ sí ìgbèkùn. Nígbà tí ó di ìrọ̀lẹ́, mo fi ọwọ́ ara mi dá odi ìlú lu, mo sì gba ibẹ̀ jáde lóru. Mo gbé ẹrù mi lé èjìká níṣojú wọn.

8 Ní òwúrọ̀, OLUWA bá mi sọ̀rọ̀,

9 ó ní: “Ìwọ ọmọ eniyan, ǹjẹ́ àwọn ọmọ Israẹli, àwọn ọlọ̀tẹ̀ wọnyi kò bèèrè lọ́wọ́ rẹ pé kí ni ò ń ṣe?

10 Wí fún wọn pé, ‘Èmi OLUWA Ọlọrun sọ pé àsọtẹ́lẹ̀ yìí ń bá àwọn olórí Jerusalẹmu ati àwọn eniyan Israẹli tí ó kù ninu rẹ̀ wí.’

11 Sọ fún wọn pé ó jẹ́ àpẹẹrẹ fún wọn. Bí o ti ṣe ni wọ́n óo ṣe wọ́n, wọn óo lọ sí ìgbèkùn.

12 Ẹni tí ó jẹ́ olórí láàrin wọn yóo gbé ẹrù rẹ̀ lé èjìká ní alẹ́, yóo sì jáde kúrò nílùú. Yóo dá odi ìlú lu, yóo gba ibẹ̀ jáde. Yóo fi nǹkan bojú kí ó má ba à rí ilẹ̀.

13 N óo na àwọ̀n mi lé e lórí, yóo sì kó sinu tàkúté tí mo dẹ sílẹ̀. N óo mú un lọ sí Babiloni ní ilẹ̀ àwọn ará Kalidea. Kò ní fi ojú rí i, bẹ́ẹ̀ sì ni ibẹ̀ ni yóo kú sí.

14 Gbogbo àwọn tí wọ́n yí i ká ni n óo túká: gbogbo àwọn olùrànlọ́wọ́ ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ ni n óo sì jẹ́ kí ogun máa lé lọ.

15 “Wọn óo mọ̀ pé èmi ni OLUWA, nígbà tí mo bá fọ́n wọn ká sí ààrin àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, tí mo tú wọn ká sórí ilẹ̀ ayé.

16 N óo jẹ́ kí díẹ̀ ninu wọn bọ́ lọ́wọ́ ogun, ati ìyàn ati àjàkálẹ̀ àrùn, kí wọ́n lè ròyìn gbogbo ohun ìríra wọn láàrin àwọn tí wọn óo lọ máa gbé; wọn óo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA.”

Àmì Wolii Tí Ń Gbọ̀n

17 OLUWA tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní:

18 “Ìwọ ọmọ eniyan, máa jẹun. Bí o tí ń jẹun lọ́wọ́, jẹ́ kí ọwọ́ rẹ máa gbọ̀n, kí o sì máa fi ìwárìrì ati ìbẹ̀rù mu omi rẹ.

19 Kí o wá sọ fún àwọn tí ń gbé ilẹ̀ náà pé, ‘OLUWA Ọlọrun sọ nípa àwọn ará Jerusalẹmu ati àwọn tí ń gbé ilẹ̀ Israẹli pé: Pẹlu ìpayà ni wọn óo máa fi jẹun, tí wọn óo sì máa fi mu omi, nítorí pé ilẹ̀ wọn yóo di ahoro nítorí ìwà ipá tí àwọn tí ń gbé inú rẹ̀ ń hù.

20 Àwọn ìlú tí eniyan ń gbé yóo di òkítì àlàpà, gbogbo ilẹ̀ náà yóo di ahoro. Ẹ óo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA.’ ”

Òwe tí Ó Lókìkí ati Iṣẹ́ tí Àwọn Eniyan kò Fẹ́ Gbọ́

21 OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní:

22 “Ìwọ ọmọ eniyan, kí ló dé tí wọ́n máa ń pòwe ní ilẹ̀ Israẹli pé, ‘Ọjọ́ ń pẹ́ sí i, gbogbo ìran tí àwọn aríran rí sì já sí òfo.’

23 Nítorí náà, sọ fún wọn pé èmi, OLUWA Ọlọrun ní: ‘N óo fi òpin sí òwe yìí, wọn kò ní pa á ní ilẹ̀ Israẹli mọ́.’ Sọ fún wọn pé: Ọjọ́ ń súnmọ́lé tí gbogbo ìran àwọn aríran yóo ṣẹ.

24 “Nítorí pé ìran irọ́ tabi àfọ̀ṣẹ ẹ̀tàn yóo dópin láàrin àwọn ọmọ Israẹli.

25 Ṣugbọn èmi OLUWA yóo sọ ohun tí mo bá fẹ́ sọ, yóo sì ṣẹ. Kò ní falẹ̀ mọ́, ṣugbọn níṣojú ẹ̀yin ìdílé ọlọ̀tẹ̀, ni n óo sọ̀rọ̀, tí n óo sì mú un ṣẹ. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo wí bẹ́ẹ̀.”

26 OLUWA tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní,

27 “Ìwọ ọmọ eniyan, gbọ́ bí àwọn ọmọ Israẹli ti ń wí pé, Ìran ọjọ́ iwájú ni ò ń rí, o sì ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ gbọọrọ.

28 Nítorí náà, wí fún wọn pé: mo ní n kò ní fi ọ̀rọ̀ mi falẹ̀ mọ́, ṣugbọn ohun tí mo bá sọ yóo ṣẹ. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo wí bẹ́ẹ̀.”

Categories
ISIKIẸLI

ISIKIẸLI 13

Ìran Ibi Nípa Àwọn Ọkunrin Wolii Èké

1 OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní,

2 “Ìwọ ọmọ eniyan, sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún àwọn wolii Israẹli. Sọ àsọtẹ́lẹ̀, kí o sì wí fún àwọn tí wọn ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ ti ara wọn pé, ‘Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ OLUWA!’ ”

3 OLUWA Ọlọrun ní, “Ègbé ni fún àwọn òmùgọ̀ wolii tí wọn ń tẹ̀lé ìmọ̀ ara wọn láì jẹ́ pé wọ́n ríran rárá.

4 Israẹli, àwọn wolii rẹ dàbí kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ láàrin òkítì àlàpà.

5 Wọn kò gun ibi tí odi ti lanu lọ, kí wọn tún un mọ yípo agbo ilé Israẹli, kí ó má baà wó lulẹ̀ lọ́jọ́ ìdájọ́ OLUWA.

6 Wọ́n ń sọ̀rọ̀ èké, wọ́n ń woṣẹ́ irọ́, wọ́n ń wí pé, ‘OLUWA wí báyìí.’ Bẹ́ẹ̀ sì ni OLUWA kò rán wọn níṣẹ́ kankan; sibẹ wọ́n ń retí pé kí OLUWA mú ọ̀rọ̀ wọn ṣẹ.

7 Ǹjẹ́ ìran èké kọ́ ni wọ́n ń rí, tí wọ́n sì ń woṣẹ́ irọ́, nígbàkúùgbà tí wọn bá wí pé, ‘OLUWA wí báyìí’, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kò sọ̀rọ̀?”

8 Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun ní, “Nítorí ọ̀rọ̀ asán tí ẹ̀ ń sọ, ati ìran èké tí ẹ̀ ń rí, mo lòdì si yín. Bẹ́ẹ̀ ni èmi OLUWA Ọlọrun sọ.

9 N óo jẹ àwọn wolii tí wọn ń ríran èké níyà ati àwọn tí wọn ń woṣẹ́ irọ́. Wọn kò ní bá àwọn eniyan mi péjọ mọ́, tabi kí á kọ orúkọ wọn mọ́ ilé Israẹli, tabi kí wọ́n wọ ilẹ̀ Israẹli mọ́. Ẹ óo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA Ọlọrun.

10 “Nítorí pé wọ́n ti ṣi àwọn eniyan mi lọ́nà wọ́n ń wí fún wọn pé, ‘Alaafia’ nígbà tí kò sí alaafia. Ati pé nígbà tí àwọn eniyan mi ń mọ odi, àwọn wolii wọnyi ń kùn ún ní ọ̀dà funfun.

11 Wí fún àwọn tí wọn ń kun odi náà ní ọ̀dà pé, òjò ńlá ń bọ̀, yìnyín ńlá yóo bọ́, ìjì líle yóo jà.

12 Nígbà tí odi náà bá wó, ǹjẹ́ àwọn eniyan kò ní bi yín pé, ‘Ọ̀dà funfun tí ẹ fi ń kun ara rẹ̀ ńkọ́?’ ”

13 Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun ní, “N óo fi ibinu mú kí ìjì líle jà, n óo fi ìrúnú rọ ọ̀wààrà òjò ńlá, n óo mú kí yìnyín ńláńlá bọ́ kí ó pa á run.

14 N óo wó ògiri tí ẹ kùn lẹ́fun, n óo wó o lulẹ̀ débi pé ìpìlẹ̀ rẹ̀ yóo hàn síta. Nígbà tí ó bá wó, ẹ óo ṣègbé ninu rẹ̀. Ẹ óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA.

15 “Bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe tẹ́ ibinu mi lọ́rùn lára odi náà ati àwọn tí wọn ń kùn ún lẹ́fun. N óo wí fun yín pé, odi kò sí mọ́, àwọn tí wọn ń kùn ún lẹ́fun náà kò sì sí mọ́;

16 àwọn wolii Israẹli tí wọn ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa Jerusalẹmu tí wọn ń ríran alaafia nípa rẹ̀, nígbà tí kò sí alaafia. Bẹ́ẹ̀ ni èmi OLUWA Ọlọrun wí.”

Ìran Ibi Nípa Àwọn Obinrin Wolii Èké

17 OLUWA ní, “Ìwọ ọmọ eniyan, dojú kọ àwọn ọmọbinrin àwọn eniyan rẹ, tí wọn ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ ti ọkàn wọn. Sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa wọn, kí o wí pé

18 èmi OLUWA Ọlọrun sọ pé, ‘Ègbé ni fún àwọn obinrin tí wọn ń so ẹ̀gbà òògùn mọ́ gbogbo eniyan lọ́wọ́, tí wọ́n sì ń ṣe ìbòjú fún gbogbo eniyan, kí ọwọ́ wọn lè ká eniyan. Ṣé ẹ̀ ń dọdẹ ẹ̀mí àwọn eniyan mi ni, kí ẹ lè dá àwọn ẹlòmíràn sí fún èrè ara yín?

19 Ẹ ti sọ mí di ẹni ìríra lójú àwọn eniyan mi nítorí ẹ̀kún ọwọ́ ọkà baali mélòó kan ati èérún burẹdi. Ẹ̀ ń pa àwọn tí kò yẹ kí ẹ pa, ẹ sì ń dá àwọn tí kò yẹ kí wọ́n wà láàyè sí, nípa irọ́ tí ẹ̀ ń pa fún àwọn eniyan mi, tí wọn ń fetí sí irọ́ yín.’

20 “Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun ní, ‘Mo kórìíra àwọn ẹ̀gbà ọwọ́, òògùn tí ẹ fi ń dọdẹ ẹ̀mí eniyan. N óo já wọn kúrò lápá yín, n óo sì tú àwọn ẹ̀mí tí ẹ dè sílẹ̀ bí ẹyẹ.

21 N óo ya ìbòjú yín kúrò, n óo gba àwọn eniyan mi lọ́wọ́ yín. Wọn kò ní jẹ́ ohun ọdẹ lọ́wọ́ yín mọ́, ẹ óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA.’

22 “Nítorí pé ẹ̀ ń fi àrékérekè ba àwọn olódodo lọ́kàn jẹ́, nígbà tí n kò fẹ́ bà wọ́n lọ́kàn jẹ́; ẹ sì ń ṣe onígbọ̀wọ́ àwọn eniyan burúkú kí wọn má baà yipada lọ́nà ibi wọn, kí wọn sì rí ìgbàlà.

23 Nítorí náà, ẹ kò ní ríran èké mọ́, ẹ kò sì ní woṣẹ́ mọ́. N óo gba àwọn eniyan mi lọ́wọ́ yín, nígbà náà, ni ẹ óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA.”

Categories
ISIKIẸLI

ISIKIẸLI 14

Ọlọrun Fi Ìbọ̀rìṣà Gégùn-ún

1 Àwọn àgbààgbà Israẹli kan tọ̀ mí wá, wọ́n jókòó siwaju mi.

2 OLUWA bá bá mi sọ̀rọ̀,

3 ó ní: “Ìwọ ọmọ eniyan, àwọn ọkunrin wọnyi kó oriṣa wọn lé ọkàn, wọ́n sì gbé ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ tí ń múni kọsẹ̀ siwaju wọn. Ṣé wọ́n rò pé n óo dá wọn lóhùn tí wọ́n bá wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ mi?

4 “Nítorí náà, sọ fún wọn pé, èmi OLUWA Ọlọrun ní ẹnikẹ́ni ninu àwọn ọmọ Israẹli tí ó bá kó oriṣa rẹ̀ lé ọkàn tí ó gbé ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ tí ń múni kọsẹ̀ siwaju rẹ̀, tí ó wá tọ wolii wá, èmi OLUWA fúnra mi ni n óo dá a lóhùn gẹ́gẹ́ bí ọpọlọpọ oriṣa rẹ̀.

5 Bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe, kí n lè dá ọkàn àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n ṣáko kúrò lọ́dọ̀ mi nítorí oriṣa wọn pada.

6 “Nítorí náà, sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé èmi OLUWA Ọlọrun ní kí wọn ronupiwada, kí wọn pada lẹ́yìn àwọn oriṣa wọn, kí wọn yíjú kúrò lára àwọn nǹkan ìríra tí wọn ń bọ

7 “Nítorí pé bí ẹnikẹ́ni ninu ẹ̀yin ọmọ Israẹli tabi ninu àwọn àlejò tí wọ́n wọ̀ ní ilẹ̀ Israẹli bá ya ara rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ mi, tí ó Kó oriṣa rẹ̀ lé ọkàn, tí ó sì gbé ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ tí ń múni kọsẹ̀ ka iwájú rẹ̀, tí ó wá tọ wolii lọ láti wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ rẹ̀ ní orúkọ mi, èmi OLUWA fúnra mi ni n óo dá a lóhùn.

8 N óo dójú lé olúwarẹ̀, n óo fi ṣe ẹni àríkọ́gbọ́n ati àmúpòwe. N óo pa á run láàrin àwọn eniyan mi; ẹ óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA.

9 “Bí wolii kan bá jẹ́ kí á ṣi òun lọ́nà, tí ó sì sọ̀rọ̀, a jẹ́ pé èmi OLUWA ni mo jẹ́ kí wolii náà ṣìnà, N óo na ọwọ́ ìyà sí i, n óo sì pa á run kúrò láàrin àwọn ọmọ Israẹli, eniyan mi.

10 Àwọn mejeeji yóo jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Irú ìyà kan náà ni n óo fi jẹ wolii alára ati ẹni tí ó lọ wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ rẹ̀.

11 N óo ṣe bẹ́ẹ̀, kí ẹ̀yin ọmọ Israẹli má baà ṣáko kúrò lọ́dọ̀ mi mọ́, tabi kí ẹ máa fi ẹ̀ṣẹ̀ sọ ara yín di aláìmọ́. Ṣugbọn kí ẹ lè jẹ́ eniyan mi, kí n sì jẹ́ Ọlọrun yín. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

Noa, Daniẹli ati Jobu

12 OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní,

13 “Ìwọ ọmọ eniyan, bí orílẹ̀-èdè kan bá ṣẹ̀ mí, tí wọ́n ṣe aiṣootọ, tí mo bá run gbogbo oúnjẹ wọn, tí mo mú kí ìyàn jà ní ilẹ̀ náà, tí mo sì run ati eniyan ati ẹranko inú rẹ̀,

14 bí àwọn ọkunrin mẹta wọnyi: Noa, Daniẹli ati Jobu bá tilẹ̀ wà ninu rẹ̀, ẹ̀mí wọn nìkan ni wọn óo lè fi òdodo wọn gbàlà. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

15 “Bí mo bá jẹ́ kí àwọn ẹranko burúkú já wọ orílẹ̀-èdè náà, kí wọ́n pa wọ́n lọ́mọ jẹ, tí wọ́n sọ ilẹ̀ náà di ahoro, tí ẹnikẹ́ni kò lè gba ibẹ̀ kọjá mọ́, nítorí àwọn ẹranko tí wọ́n wà níbẹ̀,

16 bí Noa, ati Daniẹli ati Jobu bá tilẹ̀ wà níbẹ̀, bí èmi OLUWA Ọlọrun fi ara mi búra pé, wọn kò ní lè gba ọmọkunrin tabi ọmọbinrin wọn là. Ara wọn nìkan ni wọn yóo lè gbàlà, ilẹ̀ náà yóo sì di ahoro.

17 Bí mo bá mú kí ogun jà ní ilẹ̀ náà, tí mo sì pa eniyan ati ẹranko run ninu rẹ̀,

18 bí àwọn ọkunrin mẹta náà bá tilẹ̀ wà níbẹ̀, bí èmi OLUWA ti wà láàyè, wọn kò ní lè gba ọmọkunrin tabi ọmọbinrin wọn là. Ara wọn nìkan ni wọn yóo lè gbàlà.

19 “Tabi bí mo bá rán àjàkálẹ̀ àrùn sí orílẹ̀-èdè náà, tí mo sì fi ibinu bá a jà, débi pé eniyan kú níbẹ̀, tí mo pa ati eniyan ati ẹranko run ninu rẹ̀,

20 bí Noa, Daniẹli ati Jobu bá tilẹ̀ wà níbẹ̀, èmi OLUWA Ọlọrun fi ara mi búra pé, wọn kò ní lè gba ọmọkunrin tabi ọmọbinrin wọn là. Ara wọn nìkan ni wọn yóo lè fi òdodo wọn gbàlà.”

21 Nítorí OLUWA Ọlọrun ní, “Báwo ni yóo ti wá burú tó nisinsinyii tí mo rán ìjẹníyà burúkú mẹrin wọnyi sí Jerusalẹmu: ogun, ìyàn, ẹranko burúkú ati àjàkálẹ̀ àrùn láti pa eniyan ati ẹranko run ninu rẹ̀.

22 Sibẹ bí a bá rí àwọn tí wọ́n yè ninu wọn lọkunrin ati lobinrin, tí wọ́n bá wá sọ́dọ̀ rẹ, tí o rí ìwà ati ìṣe wọn, o óo gbà pé mo jàre ní ti ibi tí mo jẹ́ kí ó ṣẹlẹ̀ sí Jerusalẹmu.

23 Wọn yóo jẹ́ ìtùnú fún ọ nígbà tí o bá rí ìwà ati ìṣe wọn, O óo sì mọ̀ pé bí kò bá nídìí, n kò ní ṣe gbogbo ohun tí mo ṣe sí wọn. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

Categories
ISIKIẸLI

ISIKIẸLI 15

Òwe Nípa Igi Àjàrà

1 OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní:

2 “Ìwọ ọmọ eniyan, ọ̀nà wo ni ẹ̀ka igi àjàrà gbà dára ju ẹ̀ka igi yòókù lọ; àní igi àjàrà tí ó wà láàrin àwọn igi inú igbó?

3 Ǹjẹ́ ẹnìkan a máa fi igi rẹ̀ ṣe ohunkohun? Àbí wọn a máa gé lára rẹ̀ kí wọn fi gbẹ́ èèkàn tí wọ́n fi ń so nǹkan mọ́lẹ̀?

4 Iná ni wọ́n ń fi í dá, nígbà tí iná bá jó o lórí, tí ó jó o nídìí, tí ó sì sọ ààrin rẹ̀ di èédú, ṣé ó tún ṣe é fi ṣe ohunkohun?

5 Nígbà tí ó wà ní odidi, kò wúlò fún nǹkankan. Nígbà tí iná ti jó o, tí ó ti di èédú, ṣé eniyan tún lè fi ṣe ohunkohun?”

6 Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun ní, “Bí ẹ̀ka àjàrà tí mo sọ di igi ìdáná láàrin àwọn igi, bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe àwọn tí ń gbé Jerusalẹmu.

7 N óo dójú lé wọn, bí wọn tilẹ̀ yọ jáde ninu iná, sibẹsibẹ iná ni yóo jó wọn. Nígbà tí mo bá dójú lé wọn, ẹ óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA.

8 N óo sọ ilẹ̀ náà di ahoro nítorí pé wọ́n ti hùwà aiṣootọ. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

Categories
ISIKIẸLI

ISIKIẸLI 16

Ìtàn Jerusalẹmu

1 OLUWA tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní:

2 “Ìwọ ọmọ eniyan, fi nǹkan ìríra tí Jerusalẹmu ń ṣe hàn án,

3 kí o sì sọ fún un pé, OLUWA Ọlọrun sọ nípa Jerusalẹmu pé:

“Ilẹ̀ Kenaani ni a bí ọ sí; ibẹ̀ ni orísun rẹ. Ará Amori ni baba rẹ ará Hiti sì ni ìyá rẹ.

4 Bí wọn ṣe bí ọ nìyí: nígbà tí wọ́n bí ọ, wọn kò dá ìwọ́ rẹ, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò fi omi wẹ̀ ọ́. Wọn kò fi iyọ̀ pa ọ́ lára, wọn kò sì fi aṣọ wé ọ.

5 Ẹnikẹ́ni kò wò ọ́ lójú, kí ó ṣàánú rẹ, kí ó ṣe ọ̀kan kan ninu àwọn nǹkan wọ̀n-ọn-nì fún ọ. Ṣugbọn wọ́n gbé ọ sọ sinu pápá, nítorí pé wọ́n kórìíra rẹ ní ọjọ́ tí wọ́n bí ọ.

6 “Bí mo tí ń rékọjá lọ lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ, mo rí ọ tí ò ń ta ẹsẹ̀ ninu ẹ̀jẹ̀. Bí o tí ń yí ninu ẹ̀jẹ̀, mo bá sọ fún ọ pé kí o yè,

7 kí o sì dàgbà bí irúgbìn oko. Ni o bá dàgbà, o ga, o sì di wundia, ọyàn rẹ yọ, irun rẹ sì hù, sibẹ o wà ní ìhòòhò.

8 “Ìgbà tí mo tún kọjá lọ́dọ̀ rẹ, tí mo tún wò ọ́, o ti dàgbà o tó gbé. Mo bá da aṣọ mi bò ọ́, mo fi bo ìhòòhò rẹ. Mo ṣe ìlérí fún ọ, mo bá ọ dá majẹmu, o sì di tèmi. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

9 “Lẹ́yìn náà, mo mú omi, mo wẹ̀ ọ́; mo fọ ẹ̀jẹ̀ kúrò lára rẹ, mo sì fi òróró pa ọ́ lára.

10 Mo wá wọ̀ ọ́ ní aṣọ tí wọ́n ṣe ọnà sí lára, mo wọ̀ ọ́ ní bàtà aláwọ. Mo wọ̀ ọ́ ní aṣọ funfun, mo sì dá ẹ̀wù siliki fún ọ.

11 Mo ṣe ọ́ lọ́ṣọ̀ọ́, mo fi ẹ̀gbà sí ọ lọ́wọ́; mo sì fi ìlẹ̀kẹ̀ sí ọ lọ́rùn.

12 Mo fi òrùka sí ọ nímú, mo fi yẹtí sí ọ létí, mo sì fi adé tí ó lẹ́wà dé ọ lórí.

13 Bẹ́ẹ̀ ni mo fi wúrà ati fadaka ṣe ọ̀ṣọ́ sí ọ lára. Aṣọ funfun ati siliki tí wọ́n ṣe iṣẹ́ ọnà sí lára ni mo dá fún ọ. Ò ń jẹ burẹdi tí ó dùn, tí wọ́n fi ìyẹ̀fun tí ó kúnná ṣe, ò ń lá oyin ati òróró; o dàgbà, o sì di arẹwà, o dàbí Ọbabinrin.

14 Òkìkí ẹwà rẹ wá kàn ká gbogbo orílẹ̀-èdè; o dára nítorí pé èmi ni mo fún ọ ní ẹwà. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

15 “Ṣugbọn o gbójú lé ẹwà rẹ; o di alágbèrè ẹ̀sìn nítorí òkìkí rẹ, o sì ń bá gbogbo àwọn eniyan tí wọn ń kọjá ṣe àgbèrè.

16 O mú ninu àwọn aṣọ rẹ, o fi ṣe ojúbọ aláràbarà, o sì ń ṣe àgbèrè ẹ̀sìn níbẹ̀. Irú nǹkan bẹ́ẹ̀ kò ṣẹlẹ̀ rí, bẹ́ẹ̀ ni kò ní ṣẹlẹ̀ mọ́.

17 O mú ninu àwọn ohun ọ̀ṣọ́ wúrà ati ti fadaka rẹ, tí mo fún ọ, o fi wọ́n ṣe ère ọkunrin, o sì ń bá wọn ṣe àgbèrè.

18 O mú aṣọ rẹ tí a ṣe ọnà sí lára, o dà á bò wọ́n. O gbé òróró ati turari mi kalẹ̀ níwájú wọn.

19 Bẹ́ẹ̀ náà ni oúnjẹ tí mo fún ọ. Mo fún ọ ní ìyẹ̀fun tí ó kúnná, ati òróró, ati oyin pé kí o máa jẹ, ṣugbọn o fi rú ẹbọ olóòórùn dídùn sí wọn. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

20 “O mú àwọn ọmọ rẹ ọkunrin ati àwọn ọmọ rẹ obinrin tí o bí fún mi, o fi wọ́n rú ẹbọ ohun jíjẹ fún àwọn oriṣa. Ṣé ẹ̀ṣẹ̀ kékeré ni o pe ẹ̀ṣẹ̀ àgbèrè ẹ̀sìn rẹ,

21 tí o fi ọ̀bẹ dú àwọn ọmọ mi, o fi wọ́n rú ẹbọ sísun sí àwọn oriṣa?

22 Nígbà tí ò ń ṣe àgbèrè ati gbogbo nǹkan ìríra rẹ, o kò ranti ìgbà èwe rẹ, nígbà tí o wà ní ìhòòhò goloto, tí ò ń ta ẹsẹ̀ ninu ẹ̀jẹ̀!”

Ìgbé-Ayé Jerusalẹmu Gẹ́gẹ́ Bí Alágbèrè Ẹ̀sìn

23 OLUWA Ọlọrun ní, “Lẹ́yìn gbogbo iṣẹ́ ibi wọnyi, o gbé! O gbé!

24 O mọ ilé gíga fún ara rẹ ní gbogbo gbàgede, o tẹ́ ìtẹ́ gíga fún ara rẹ ní ìta gbangba.

25 O mọ ìtẹ́ gíga ní òpin gbogbo òpópó. O sì ń ba ẹwà rẹ jẹ́ níbẹ̀, ò ń ta ara rẹ fún gbogbo ọkunrin tí wọn ń kọjá, o sì sọ àgbèrè rẹ di pupọ.

26 O tún ṣe àgbèrè ẹ̀sìn pẹlu àwọn ará Ijipti, àwọn aládùúgbò rẹ, oníṣekúṣe. Ò ń mú kí ìwà àgbèrè rẹ pọ̀ sí i láti mú mi bínú.

27 “Ọwọ́ mi wá tẹ̀ ọ́, mo mú ọ kúrò ninu ẹ̀tọ́ rẹ. Mo jẹ́ kí àwọn ọ̀tá rẹ fi ìwọ̀ra gba ohun ìní rẹ, àwọn ará Filistini tí ìwà burúkú rẹ ń tì lójú.

28 “O bá àwọn ará Asiria ṣe àgbèrè ẹ̀sìn pẹlu, nítorí pé o kò ní ìtẹ́lọ́rùn sibẹ, lẹ́yìn gbogbo àgbèrè tí o ṣe pẹlu wọn, o kò ní ìtẹ́lọ́rùn.

29 O tún ṣe àgbèrè lọpọlọpọ pẹlu àwọn oníṣòwò ará ilẹ̀ Kalidea, sibẹsibẹ, kò tẹ́ ọ lọ́rùn.”

30 OLUWA Ọlọrun ní ọkàn rẹ ti kún fún ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ jù! Ó ń wò ọ́ bí o tí ń ṣe gbogbo nǹkan wọnyi bí alágbèrè tí kò nítìjú!

31 O mọ ilé oriṣa sí òpin gbogbo òpópó, o sì ń kọ́ ibi ìrúbọ sí gbogbo gbàgede. Sibẹ o kò ṣe bí àwọn alágbèrè, nítorí pé o kò gba owó.

32 Ìwọ iyawo onípanṣágà tí ò ń kó àwọn ọkunrin ọlọkunrin wọlé dípò ọkọ rẹ.

33 Ọkunrin níí máa ń fún àwọn aṣẹ́wó ní ẹ̀bùn, ṣugbọn ní tìrẹ, ìwọ ni ò ń fún àwọn olólùfẹ́ rẹ lẹ́bùn. O fi ń tù wọ́n lójú, kí wọ́n lè máa wá bá ọ ṣe àgbèrè láti ibi gbogbo.

34 Àgbèrè tìrẹ yàtọ̀ sí ti àwọn aṣẹ́wó yòókù, kò sí ẹni tí ń wá ọ láti bá ọ ṣe àgbèrè; ìwọ ni ò ń fún ọkunrin ní ẹ̀bùn dípò kí wọ́n fún ọ! Èyí ni àgbèrè tìrẹ fi yàtọ̀ sí ti àwọn ẹlòmíràn.

Ìdájọ́ Ọlọrun lórí Jerusalẹmu

35 Nítorí náà, ìwọ aṣẹ́wó yìí, gbọ́ ohun tí OLUWA wí.

36 OLUWA Ọlọrun ní, “Ìwà ìtìjú rẹ ti hàn sí gbangba, o bọ́ra sí ìhòòhò níta, nígbà tí ò ń bá àwọn olólùfẹ́ rẹ ṣe àgbèrè, tí ò ń bọ àwọn oriṣa rẹ, o sì pa àwọn ọmọ rẹ, o fi wọ́n rúbọ sí àwọn oriṣa.

37 Wò ó! N óo kó gbogbo àwọn olólùfẹ́ rẹ, tí inú rẹ dùn sí jọ, ati àwọn tí o fẹ́ràn ati àwọn tí o kórìíra, ni n óo kó wá láti dojú kọ ọ́ ní gbogbo ọ̀nà. N óo tú ọ sí ìhòòhò lójú wọn, kí wọ́n lè rí ìhòòhò rẹ.

38 N óo ṣe ìdájọ́ fún ọ bí wọn tí ń ṣe ìdájọ́ fún àwọn obinrin tí wọ́n kọ ọkọ sílẹ̀, tabi àwọn tí wọ́n paniyan. N óo fi ìtara ati ibinu gbẹ̀san ìpànìyàn lára rẹ.

39 N óo fi ọ́ lé àwọn olólùfẹ́ rẹ lọ́wọ́, wọn óo wó ilé oriṣa ati ibi ìrúbọ rẹ palẹ̀. Wọn óo tú aṣọ rẹ, wọn óo gba àwọn ohun ọ̀ṣọ́ rẹ, wọn yóo sì fi ọ́ sílẹ̀ ní ìhòòhò.

40 “Wọn óo kó àwọn ọmọ ogun wá bá ọ, wọn óo sọ ọ́ lókùúta, wọn óo sì fi idà wọn gé ọ sí wẹ́wẹ́.

41 Wọn óo dáná sun àwọn ilé rẹ, wọn óo sì ṣe ìdájọ́ fún ọ lójú àwọn obinrin pupọ. N kò ní jẹ́ kí o ṣe àgbèrè mọ́, bẹ́ẹ̀ ni n kò ní jẹ́ kí o fún àwọn olólùfẹ́ rẹ ní ẹ̀bùn mọ́.

42 Bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe tẹ́ ibinu mi lọ́rùn lára rẹ, n kò sì ní jowú nítorí rẹ mọ́. Ara mi yóo rọlẹ̀, inú kò sì ní bí mi mọ́.

43 Nítorí pé o kò ranti ìgbà èwe rẹ, ṣugbọn o mú mi bínú nítorí nǹkan wọnyi. Nítorí náà n óo da èrè iṣẹ́ ọwọ́ rẹ lé ọ lórí. Ṣé o kò tún ti fi ìwà ainitiju kún ìwà ìríra rẹ?” OLUWA Ọlọrun ni ó sọ bẹ́ẹ̀.

Bí Ìyá Ti Rí Ni Ọmọ Rẹ̀ Obinrin Náà Rí

44 OLUWA ní: “Gbogbo eniyan ni yóo máa pa òwe yìí mọ́ ìwọ Jerusalẹmu pé: ‘Òwú ìyá gbọ̀n ni ọmọ óo ran, bí ìyá bá ti rí ni ọmọ rẹ̀ obinrin yóo rí.’

45 Ọmọ bíbí inú ìyá rẹ ni ọ́, tí kò bìkítà fún ọkọ ati àwọn ọmọ rẹ̀. Ìwà kan náà ni ó wà lọ́wọ́ ìwọ ati àwọn arabinrin rẹ, àwọn náà kò ka ọkọ ati àwọn ọmọ wọn sí. Ará Hiti ni ìyá rẹ, ará Amori sì ni baba rẹ.

46 “Samaria ni ẹ̀gbọ́n rẹ, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ń gbé ìhà àríwá. Sodomu ni àbúrò rẹ, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ń gbé ìhà gúsù.

47 Títẹ̀lé ìṣe wọn nìkan kò tẹ́ ọ lọ́rùn, bẹ́ẹ̀ ni ṣíṣe ohun ìríra bíi tiwọn kò tó ọ. Láìpẹ́ ọjọ́, ìwà tìrẹ gan-an yóo burú ju tiwọn lọ.

48 “Èmi OLUWA Ọlọrun fi ara mi búra pé, Sodomu arabinrin rẹ ati àwọn ọmọ rẹ̀ obinrin kò tíì ṣe tó ohun tí ìwọ ati àwọn ọmọbinrin rẹ ṣe.

49 Ohun tí Sodomu arabinrin rẹ ṣe tí kò dára ni pé: Òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ obinrin ní ìgbéraga. Wọ́n ní oúnjẹ lọpọlọpọ, ara sì rọ̀ wọ́n, ṣugbọn wọn kò ran talaka ati aláìní lọ́wọ́.

50 Wọ́n gbéraga, wọ́n sì ṣe nǹkan ìríra níwájú mi. Nítorí náà, nígbà tí mo rí ohun tí wọn ń ṣe, mo pa wọ́n run.

51 “Ẹ̀ṣẹ̀ tí Samaria dá kò tó ìdajì èyí tí ìwọ dá, ohun ìríra tí o ṣe sì jù tiwọn lọ. O ti mú kí arabinrin rẹ dàbí olódodo lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ, nítorí pé nǹkan ìríra tí o ṣe pọ̀ pupọ ju tirẹ̀ lọ.

52 Ó yẹ kí ojú ti ìwọ pàápàá, nítorí o ti jẹ́ kí ìdájọ́ gbe àwọn arabinrin rẹ, nítorí nǹkan ìríra tí o ṣe ju tiwọn lọ. Ọ̀nà wọn tọ́ ju tìrẹ lọ, nítorí náà, ó yẹ kí ojú tì ọ́, nítorí o ti mú kí àwọn arabinrin rẹ dàbí olódodo lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ.”

Ìtura Yóo Pada sí Sodomu ati Samaria

53 OLUWA sọ níti Jerusalẹmu pé, “N óo dá ire wọn pada: ire Sodomu ati ti àwọn ọmọ rẹ̀ obinrin ati ire Samaria ati ti àwọn ọmọ rẹ̀ obinrin. N óo dá ire tìrẹ náà pada pẹlu tiwọn.

54 Kí ojú lè tì ọ́ fún gbogbo ohun tí o ṣe tí o fi dá wọn lọ́kàn le.

55 Ní ti àwọn arabinrin rẹ: Sodomu ati àwọn ọmọ rẹ̀ obinrin yóo pada sí ibùgbé wọn, Samaria ati àwọn ọmọ rẹ obinrin yóo pada sí ibùgbé wọn, ìwọ ati àwọn ọmọ rẹ̀ obinrin náà yóo pada sí ibùgbé yín.

56 Ṣebí yẹ̀yẹ́ ni ò ń fi Sodomu arabinrin rẹ ṣe ní àkókò tí ò ń gbéraga,

57 kí ó tó di pé àṣírí ìwà burúkú rẹ wá tú? Nisinsinyii ìwọ náà ti dàbí rẹ̀; o ti di ẹni yẹ̀yẹ́ lọ́wọ́ àwọn ọmọbinrin Edomu ati àwọn tí ó wà ní agbègbè wọn, ati lọ́wọ́ àwọn ọmọbinrin Filistini, ati àwọn tí wọ́n yí ọ ká, tí wọn ń kẹ́gàn rẹ.

58 O óo jìyà nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ ati àwọn nǹkan ìríra tí o ṣe. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

Majẹmu Ayérayé

59 Láìṣe àní, àní, OLUWA Ọlọrun ní, “N óo ṣe sí ọ, bí ìwà rẹ. O kò ka ìbúra mi sí, o sì ti yẹ majẹmu mi.

60 Sibẹsibẹ, n óo ranti majẹmu tí mo bá ọ dá ní ìgbà èwe rẹ. N óo sì bá ọ dá majẹmu tí kò ní yẹ̀ títí lae.

61 O óo wá ranti gbogbo ìwà rẹ, ojú yóo sì tì ọ́ nígbà tí mo bá mú ẹ̀gbọ́n rẹ obinrin ati àbúrò rẹ obinrin, tí mo sì fà wọ́n lé ọ lọ́wọ́ bí ọmọ; ṣugbọn tí kò ní jẹ́ pé torí majẹmu tí mo bá ọ dá ni.

62 N óo fìdí majẹmu tí mo bá ọ dá múlẹ̀. O óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA.

63 Kí o lè ranti, kí ìdààmú sì bá ọ, kí ìtìjú má jẹ́ kí o lè lanu sọ̀rọ̀ mọ́; nígbà tí mo bá dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

Categories
ISIKIẸLI

ISIKIẸLI 17

Òwe Nípa Àwọn Ẹyẹ Idì ati Àjàrà

1 OLUWA tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní,

2 “Ìwọ ọmọ eniyan, pa àlọ́ kan kí o sì fi òwe bá àwọn ọmọ Israẹli sọ̀rọ̀.

3 Wí fún wọn pé, OLUWA Ọlọrun ní idì ńlá kan wá sí Lẹbanoni, apá rẹ̀ tóbi, ìrù rẹ̀ sì gùn, ó sì ní ìyẹ́ aláràbarà. Ó bá bà lé ṣóńṣó orí igi kedari kan,

4 ó ṣẹ́ ẹ̀ka rẹ̀ lórí, ó gbé e lọ sí ilẹ̀ àwọn oníṣòwò; ó fi sí ìlú àwọn tí ń ta ọjà.

5 Lẹ́yìn náà, ó mú ninu èso ilẹ̀ náà, ó gbìn ín sí ilẹ̀ kan tí ó lọ́ràá, ní ẹ̀bá odò. Ó gbìn ín bí wọn tíí gbin igi wilo.

6 Igi yìí hù, ó dàbí àjàrà tí kò ga, ṣugbọn tí ó tàn kálẹ̀. Ẹ̀ka rẹ̀ nà sọ́dọ̀ idì yìí lókè, ṣugbọn gbòǹgbò rẹ̀ kò kúrò níbi tí ó wà. Ó di àjàrà, ó yọ ẹ̀ka, ó sì rúwé.

7 “Idì ńlá mìíràn tún wà, apá rẹ̀ tóbi, ìyẹ́ rẹ̀ sì pọ̀ lọpọlọpọ. Àjàrà yìí bá kọ orí gbòǹgbò ati ẹ̀ka rẹ̀ sí ọ̀dọ̀ idì ńlá yìí, kí Idì náà lè máa bomi rin ín.

8 Idì yìí bá hú u níbi tí wọ́n gbìn ín sí, ó lọ gbìn ín sí ilẹ̀ kan tí ó lọ́ràá lẹ́bàá odò, kí ó lè yọ ẹ̀ka, kí ó so èso, kí ó sì di àjàrà ńlá tí ó níyì.

9 “Sọ fún wọn pé, èmi OLUWA Ọlọrun ní kí o bèèrè lọ́wọ́ wọn pé, ‘Ṣé àjàrà yìí yóo ṣe dáradára? Ṣé idì ti àkọ́kọ́ kò ní fa gbòǹgbò rẹ̀ tu, kí ó gé ẹ̀ka rẹ̀, kí àwọn ewé rẹ̀ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ yọ sì rọ?’ Kò ṣẹ̀ṣẹ̀ nílò alágbára tabi ọ̀pọ̀ eniyan, láti fà á tu tigbòǹgbò tigbòǹgbò.

10 Nígbà tí wọ́n bá tún un gbìn ǹjẹ́ yóo yè? Ṣé kò ní gbẹ patapata nígbà tí afẹ́fẹ́ ìlà oòrùn bá fẹ́ lù ú? Yóo gbẹ níbi tí wọ́n gbìn ín sí.”

Ìtumọ̀ Òwe Náà

11 Lẹ́yìn náà, OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní,

12 “Bi àwọn ọlọ̀tẹ̀ wọnyi pé, ṣé wọn kò mọ ìtumọ̀ òwe wọnyi ni? Sọ pé ọba Babiloni wá sí Jerusalẹmu, ó sì kó ọba ati àwọn ìjòyè rẹ̀ lọ sí ọ̀dọ̀ ara rẹ̀ ní Babiloni.

13 Ó mú ọ̀kan ninu àwọn ìdílé ọba, ó bá a dá majẹmu, ó sì mú kí ó búra. Ó ti kọ́ kó gbogbo àwọn eniyan pataki pataki ilẹ̀ náà lọ,

14 kí ilẹ̀ náà lè di ìrẹ̀sílẹ̀, kí wọ́n má sì lè gbérí mọ́, ṣugbọn kí ilẹ̀ náà lè máa ní ìtẹ̀síwájú, níwọ̀n ìgbà tí ó bá pa majẹmu ọba Babiloni mọ́.

15 Ṣugbọn ọba Juda ṣọ̀tẹ̀ sí ti Babiloni, ó rán ikọ̀ lọ sí Ijipti pé kí wọ́n fún òun ní ẹṣin ati ọpọlọpọ ọmọ ogun. Ǹjẹ́ yóo ní àṣeyọrí? Ṣé ẹni tí ń ṣé irú èyí lè bọ́? Ṣé ó lè yẹ majẹmu náà kí ó sì bọ́ ninu rẹ̀?

16 “Èmi OLUWA fi ara mi búra pé, ní ilẹ̀ Babiloni, ní ilẹ̀ ọba tí ó fi í sórí oyè ọba tí kò náání, tí ó sì da majẹmu rẹ̀, níbẹ̀ ni yóo kú sí.

17 Farao, pẹlu ogunlọ́gọ̀ àwọn ọmọ ogun rẹ̀, ati ọpọlọpọ eniyan rẹ̀, kò ní lè ràn án lọ́wọ́ nígbà ogun; nígbà tí ogun bá dótì í, tí wọ́n sì mọ òkítì sí ara odi rẹ̀ láti pa ọpọlọpọ eniyan.

18 Kò ní sá àsálà, nítorí pé kò náání ìbúra ó sì da majẹmu, ati pé ó ti tọwọ́ bọ ìwé, sibẹsibẹ, ó tún ṣe gbogbo nǹkan tí ó ṣe.”

19 Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun ní, “Mo fi ara mi búra, n óo gbẹ̀san ìbúra mi tí kò náání lára rẹ̀, ati majẹmu mi tí ó dà.

20 N óo da àwọ̀n mi bò ó mọ́lẹ̀, pańpẹ́ mi yóo mú un, n óo sì mú un lọ sí Babiloni. Níbẹ̀ ni n óo ti ṣe ìdájọ́ rẹ̀ nítorí ìwà ọ̀tẹ̀ tí ó hù sí mi.

21 Idà ni wọn óo fi pa àwọn tí wọ́n bá sá lára àwọn ọmọ ogun rẹ̀, a óo sì fọ́n àwọn tí wọ́n bá kù ká sí gbogbo ayé, ẹ óo wá mọ̀ pé èmi OLUWA ni mo sọ̀rọ̀.”

Ìlérí Ìrètí tí Ọlọrun Ṣe

22 OLUWA Ọlọrun ní:

“Èmi fúnra mi ni n óo mú ọ̀kan ninu ẹ̀ka kan ní ṣóńṣó igi Kedari gíga,

n óo ṣẹ́ ẹ̀ka kan láti orí rẹ̀,

n óo gbìn ín sí orí òkè gíga fíofío.

23 Lórí òkè gíga Israẹli ni n óo gbìn ín sí,

kí ó lè yọ ẹ̀ka, kí ó so,

kí ó sì di igi Kedari ńlá.

Oríṣìíríṣìí ẹranko ìgbẹ́ ni yóo máa gbé abẹ́ rẹ̀.

Oríṣìíríṣìí ẹyẹ yóo pa ìtẹ́ sí abẹ́ òjìji ẹ̀ka rẹ̀.

24 Gbogbo igi inú igbó yóo mọ̀ pé

èmi, OLUWA, ni èmi í sọ igi ńlá di kékeré,

mà sì máa sọ igi kékeré di ńlá.

Mà máa sọ igi tútù di gbígbẹ,

má sì máa mú kí igi gbígbẹ pada rúwé.

Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀,

bẹ́ẹ̀ ni n óo sì ṣe.”

Categories
ISIKIẸLI

ISIKIẸLI 18

Iṣẹ́ Ẹnìkọ̀ọ̀kan

1 OLUWA tún bá mi sọ̀rọ̀, ó bi mí pé:

2 “Kí ni ẹ rí tí ẹ fi ń pa irú òwe yìí nípa ilẹ̀ Israẹli, tí ẹ̀ ń sọ pé,

‘Àwọn baba ni wọ́n jẹ èso àjàrà tí ó kan,

ni eyín fi kan àwọn ọmọ?’

3 “Mo fi ara mi búra pé, ẹ kò ní pa òwe yìí mọ́ ní ilẹ̀ Israẹli.

4 Èmi ni mo ni ẹ̀mí gbogbo eniyan, tèmi ni ẹ̀mí baba ati ẹ̀mí ọmọ; ẹni yòówù tó bá dẹ́ṣẹ̀ ni yóo kú.

5 “Bí ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ olódodo, tí ó ń ṣe ohun tí ó tọ́, tí ó sì bá òfin mu;

6 bí kò bá bá wọn jẹ ẹbọ lórí àwọn òkè, tabi kí ó bọ àwọn oriṣa ilé Israẹli; tí kò bá bá aya aládùúgbò rẹ̀ lòpọ̀, tabi kí ó bá obinrin lòpọ̀ ní àkókò tí ó ń ṣe nǹkan oṣù rẹ̀ lọ́wọ́;

7 tí kò ni ẹnikẹ́ni lára, ṣugbọn tí ó dá ohun tí onígbèsè fi ṣe ìdúró pada fún un; tí kò fi ipá jalè, tí ó ń fún ẹni tí ebi ń pa ní oúnjẹ, tí ó sì ń da aṣọ bo ẹni tí ó wà ní ìhòòhò,

8 tí kò gba owó èlé lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni, tí ó yàgò fún ẹ̀ṣẹ̀, tí ó ń dá ẹjọ́ ẹ̀tọ́ láàrin ẹni meji,

9 tí ó ń rìn ninu ìlànà mi, tí ó sì ń fi tọkàntọkàn pa òfin mi mọ́, olódodo ni irú ẹni bẹ́ẹ̀, yóo sì yè. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

10 “Bí irú ẹni bẹ́ẹ̀ bá bí ọmọ, tí ọmọ yìí ń fi ipá jalè, tí ń pa eniyan, tí kò ṣe ọ̀kankan ninu gbogbo ohun tí a kà sílẹ̀ pé baba ń ṣe,

11 ṣugbọn tí ó ń jẹ ẹbọ lórí àwọn òkè, tí ó ń bá aya aládùúgbò rẹ̀ lòpọ̀;

12 tí ń ni talaka ati aláìní lára, tí ń fi ipá jalè, tí kì í dá ohun tí onígbèsè rẹ̀ bá fi ṣe ìdúró pada fún un, tí ń bọ oriṣa, tí ń ṣe ohun ìríra,

13 tí ń gba owó èlé; ǹjẹ́ irú eniyan bẹ́ẹ̀ lè yè? Kò lè yè rárá. Nítorí pé ó ti ṣe àwọn ohun ìríra wọnyi, yóo kú ni dájúdájú; lórí ara rẹ̀ sì ni ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yóo wà.

14 “Ṣugbọn bí eniyan burúkú yìí bá bí ọmọ, tí ọmọ yìí rí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí baba rẹ̀ ń dá, tí ẹ̀rù bà á, tí kò sì ṣe bíi baba rẹ̀,

15 tí kì í jẹ ẹbọ lórí àwọn òkè, tí kò bọ àwọn oriṣa ilé Israẹli, tí kò bá aya aládùúgbò rẹ̀ lòpọ̀,

16 tí kò ṣẹ ẹnikẹ́ni; tí Kì í gba ohun ìdúró lọ́wọ́ onígbèsè, tí kì í fi ipá jalè, ṣugbọn tí ń fún ẹni tí ebi ń pa ní oúnjẹ, tí sì ń da aṣọ bo ẹni tí ó wà ní ìhòòhò,

17 tí ó yàgò fún ẹ̀ṣẹ̀, tí kì í gba owó èlé, tí ń pa òfin mi mọ́, tí sì ń rìn ninu ìlànà mi, kò ní kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ baba rẹ̀, dájúdájú yóo yè.

18 Baba rẹ̀ yóo kú ní tirẹ̀, nítorí pé ó ń fi ipá gbowó, ó ń ja arakunrin rẹ̀ lólè, ó sì ń ṣe ohun tí kò dára sí àwọn eniyan rẹ̀; nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tirẹ̀ ni yóo ṣe kú.

19 “Sibẹsibẹ ẹ̀ ń sọ pé, ‘Kí ló dé tí ọmọ kò fi ní jìyà ẹ̀ṣẹ̀ baba rẹ̀?’ Níwọ̀n ìgbà tí ọmọ bá ti ṣe ohun tí ó bá òfin mu, tí ó sì ti mú gbogbo ìlànà mi ṣẹ; dájúdájú yóo yè ni.

20 Ẹni tí ó bá ṣẹ̀ ni yóo kú: ọmọ kò ní jìyà ẹ̀ṣẹ̀ baba rẹ̀; baba kò sì ní jìyà ẹ̀ṣẹ̀ ọmọ rẹ̀. Olódodo yóo jèrè òdodo rẹ̀; bẹ́ẹ̀ sì ni eniyan burúkú yóo jèrè ìwà burúkú rẹ̀.

21 “Ṣugbọn bí eniyan burúkú bá yipada kúrò ninu gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ń dá, tí ó ń pa òfin mi mọ́, tí ó ń ṣe ohun tí ó tọ́, tí ó sì bá òfin mu, dájúdájú yóo yè ni, kò ní kú.

22 A kò ní ranti gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, yóo yè nítorí òdodo rẹ̀.”

23 OLUWA ní: “A máa ṣe pé mo ní inú dídùn sí ikú ẹlẹ́ṣẹ̀ ni? Ṣebí ohun tí mo fẹ́ ni pé kí ó yipada kúrò lọ́nà burúkú rẹ̀, kí ó sì yè.

24 “Ṣugbọn bí olódodo bá yipada kúrò ninu ìwà òdodo rẹ̀, tí ó bá bẹ̀rẹ̀ sí dẹ́ṣẹ̀, tí ó ń ṣe àwọn ohun ìríra tí àwọn eniyan burúkú ń ṣe; ṣé irú ẹni bẹ́ẹ̀ leè yè? Rárá! A kò ní ranti gbogbo òdodo rẹ̀ tí ó ti ṣe mọ́, yóo kú nítorí ìwà ọ̀tẹ̀ ati ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.

25 “Sibẹsibẹ ẹ̀ ń sọ pé, ‘Ọ̀nà OLUWA kò tọ́.’ Ẹ gbọ́, ẹ̀yin ọmọ Israẹli: ọ̀nà tèmi ni kò tọ́ ni, àbí ọ̀nà tiyín?

26 Bí olódodo bá yipada kúrò ninu ìwà òdodo rẹ̀, tí ó bẹ̀rẹ̀ sí dẹ́ṣẹ̀, yóo kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó dá.

27 Bí eniyan burúkú bá sì yipada kúrò ninu ìwà ibi rẹ̀, tí ó sì ń ṣe rere, yóo gba ẹ̀mí ara rẹ̀ là.

28 Nítorí pé ó ronú, ó sì yipada kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti ń dá, dájúdájú yóo yè, kò ní kú.

29 Sibẹsibẹ àwọn ọmọ Israẹli ń wí pé, ‘Ọ̀nà OLUWA kò tọ́.’ Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ṣé ọ̀nà mi ni kò tọ́, àbí tiyín?

30 “Nítorí náà, n óo da yín lẹ́jọ́, ẹ̀yin ọmọ Israẹli. Ìwà olukuluku ni n óo fi dá a lẹ́jọ́. Ẹ ronupiwada, kí ẹ sì yipada kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀ yín, kí ẹ̀ṣẹ̀ má baà pa yín run. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

31 Ẹ kọ gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ yín tí ẹ̀ ń dá sí mi sílẹ̀. Ẹ wá ọkàn tuntun ati ẹ̀mí tuntun fún ara yín. Kí ló dé tí ẹ fi fẹ́ kú, ẹ̀yin ọmọ ilé Israẹli?

32 N kò ní inú dídùn sí ikú ẹnikẹ́ni, nítorí náà, ẹ yipada kí ẹ lè yè. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

Categories
ISIKIẸLI

ISIKIẸLI 19

Orin Arò

1 OLUWA ní kí n sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn nítorí àwọn olórí Israẹli,

2 kí n sọ pé:

Abo kinniun pataki ni ìyá rẹ láàrin àwọn kinniun!

Ó dùbúlẹ̀ láàrin àwọn ọ̀dọ́ kinniun,

ó ń tọ́jú àwọn ọmọ rẹ̀.

3 Ó tọ́ ọ̀kan ninu àwọn ọmọ rẹ̀ dàgbà;

ó di ọ̀dọ́ kinniun.

Ó kọ́ ọ bí wọ́n tí ń ṣe ọdẹ,

ó sì ń pa eniyan jẹ.

4 Àwọn eniyan ayé gbọ́ nípa rẹ̀,

wọ́n tàn án sinu kòtò wọn.

Wọ́n fi ìwọ̀ kọ́ ọ nímú,

wọ́n sì fà á lọ sí ilẹ̀ Ijipti.

5 Nígbà tí abo kinniun náà rí i pé ọwọ́ tẹ ọmọ òun,

ati pé igbẹkẹle òun ti dòfo,

ó mú òmíràn ninu àwọn ọmọ rẹ̀,

ó tọ́ ọ di ọ̀dọ́ kinniun.

6 Ó ń yan kiri láàrin àwọn kinniun;

nítorí ó ti di ọ̀dọ́ kinniun tí ó lágbára,

ó kọ́ bí wọn tí ń ṣe ọdẹ,

ó sì ń pa eniyan jẹ.

7 Ó wó ilé ìṣọ́ wọn lulẹ̀;

ó sọ ìlú wọn di ahoro.

Ẹ̀rù ba gbogbo Ilẹ̀ náà, ati gbogbo àwọn tí ń gbé ibẹ̀,

nígbà tí wọ́n gbọ́ bíbú rẹ̀.

8 Àwọn orílẹ̀-èdè bá dójú lé e,

wọ́n dẹ tàkúté fún un ní gbogbo ọ̀nà,

wọ́n da àwọ̀n wọn bò ó,

wọ́n sì mú un ninu kòtò tí wọn gbẹ́ fún un.

9 Wọ́n sọ ìwọ̀ sí i nímú,

wọ́n gbé e jù sinu àhámọ́,

wọ́n sì fà á lọ sí ọ̀dọ̀ ọba Babiloni.

Wọ́n fi sí àtìmọ́lé,

kí wọ́n má baà gbọ́ ohùn rẹ̀ mọ́ lórí àwọn òkè Israẹli.

10 Ìyá rẹ dàbí àjàrà inú ọgbà

tí a gbìn sí ẹ̀gbẹ́ odò;

ó rúwé, ó yọ ẹ̀ka,

nítorí ó rí omi lọpọlọpọ.

11 Ẹ̀ka rẹ̀ tí ó lágbára

ni a fi gbẹ́ ọ̀pá àṣẹ fún àwọn olórí.

Ó dàgbà, ó ga fíofío, láàrin àwọn igi igbó.

Ó rí i bí ó ti ga, tí ẹ̀ka rẹ̀ sì pọ̀.

12 Ṣugbọn a fa àjàrà náà tu pẹlu ibinu,

a sì jù ú sílẹ̀.

Afẹ́fẹ́ ìlà oòrùn mú kí ó gbẹ,

gbogbo èso rẹ̀ sì rẹ̀ dànù.

Igi rẹ̀ tí ó lágbára gbẹ, iná sì jó o.

13 Nisinsinyii, a ti tún un gbìn sinu aṣálẹ̀,

ninu ilẹ̀ gbígbẹ níbi tí kò sí omi.

14 Iná ṣẹ́ lára igi rẹ̀,

ó sì jó gbogbo ẹ̀ka ati èso rẹ̀.

Kò sì ní igi tí ó lágbára mọ́,

tí a lè fi gbẹ́ ọ̀pá àṣẹ fún ọba.

Dájúdájú ọ̀rọ̀ arò ni ọ̀rọ̀ yìí, ó sì ti di orin arò.