Categories
ÌFIHÀN

ÌFIHÀN 10

Angẹli ati Ìwé-kíká Kékeré

1 Mo tún rí angẹli alágbára mìíràn, tí ó sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá. Ó fi ìkùukùu bora, òṣùmàrè sì yí orí rẹ̀ ká; ojú rẹ̀ dàbí oòrùn; ẹsẹ̀ rẹ̀ dàbí òpó iná.

2 Ó mú ìwé kékeré kan lọ́wọ́ tí ó wà ní ṣíṣí. Ó gbé ẹsẹ̀ ọ̀tún rẹ̀ lé orí òkun, ó sì gbé ti òsì lé orí ilẹ̀ ayé.

3 Ó wá bú ramúramù bíi kinniun. Nígbà tí ó bú báyìí tán, ààrá meje sán.

4 Nígbà tí ààrá meje yìí ń sán, mo fẹ́ máa kọ ohun tí wọn ń sọ sílẹ̀, ṣugbọn mo gbọ́ ohùn kan láti ọ̀run, tí ó sọ pé, “Àṣírí ni ohun tí àwọn ààrá meje yìí ń sọ, má kọ wọ́n sílẹ̀.”

5 Angẹli náà tí mo rí, tí ó gbé ẹsẹ̀ lé orí òkun, ati orí ilẹ̀, wá gbé ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ sí òkè ọ̀run,

6 ó fi ẹni tí ó wà láàyè lae ati títí laelae búra, ẹni tí ó dá ọ̀run ati ohun tí ó wà ninu rẹ̀, tí ó dá ayé ati ohun tí ó wà ninu rẹ̀, tí ó dá òkun ati ohun tí ó wà ninu rẹ̀. Ó ní kò sí ìjáfara mọ́.

7 Ní ọjọ́ tí angẹli keje bá fọhùn, nígbà tí ó bá fẹ́ fun kàkàkí tirẹ̀, àṣírí ète Ọlọrun yóo ṣẹlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ fún àwọn wolii, iranṣẹ rẹ̀.

8 Mo tún gbọ́ ohùn kan láti ọ̀run tí ó sọ fún mi pé, “Lọ gba ìwé tí ó wà ni ṣíṣí tí ó wà lọ́wọ́ angẹli tí ó dúró lórí òkun ati lórí ilẹ̀.”

9 Mo bá lọ sọ́dọ̀ angẹli náà, mo ní kí ó fún mi ní ìwé kékeré náà. Ó ní, “Gbà, kí o jẹ ẹ́. Yóo dùn ní ẹnu rẹ bí oyin, ṣugbọn yóo korò ní ikùn rẹ.”

10 Mo bá gba ìwé náà ní ọwọ́ angẹli yìí, mo bá jẹ ẹ́. Ó dùn bí oyin ní ẹnu mi. Ṣugbọn nígbà tí mo gbé e mì, ó korò ní ikùn mi.

11 Wọ́n bá sọ fún mi pé, “O níláti tún kéde fún ọ̀pọ̀ àwọn eniyan ati oríṣìíríṣìí ẹ̀yà ati àwọn orílẹ̀-èdè, ati ọpọlọpọ ìjọba.”

Categories
ÌFIHÀN

ÌFIHÀN 11

Àwọn Ẹlẹ́rìí Meji

1 Wọ́n fún mi ní ọ̀pá kan, bí èyí tí wọ́n fi ń wọn aṣọ. Wọ́n sọ fún mi pé, “Dìde! Lọ wọn Tẹmpili Ọlọrun ati pẹpẹ ìrúbọ, kí o ka iye àwọn tí wọ́n n jọ́sìn níbẹ̀.

2 Má wulẹ̀ wọn àgbàlá Tẹmpili tí ó wà lóde, nítorí a ti fi fún àwọn alaigbagbọ. Wọn yóo gba ìlú mímọ́ fún oṣù mejilelogoji.

3 N óo fún àwọn ẹlẹ́rìí mi meji láṣẹ láti kéde iṣẹ́ mi fún ọtalelẹgbẹfa (1260) ọjọ́. Aṣọ ọ̀fọ̀ ni wọn yóo wọ̀ ní gbogbo àkókò náà.”

4 Àwọn wọnyi ni igi olifi meji ati ọ̀pá fìtílà meji tí ó dúró níwájú Oluwa ayé.

5 Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ pa wọ́n lára, iná ni yóo yọ lẹ́nu wọn, yóo sì jó àwọn ọ̀tá wọn run. Irú ikú bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ ṣe wọ́n ní ibi yóo kú.

6 Wọ́n ní àṣẹ láti ti ojú ọ̀run pa, tí òjò kò fi ní rọ̀ ní gbogbo àkókò tí wọn bá ń kéde. Wọ́n tún ní àṣẹ láti sọ gbogbo omi di ẹ̀jẹ̀. Wọ́n sì lè mú kí àjàkálẹ̀ àrùn oríṣìíríṣìí bá ayé, bí wọ́n bá fẹ́.

7 Nígbà tí wọ́n bá parí ẹ̀rí tí wọn níí jẹ́, ẹranko tí ó jáde láti inú kànga tí ó jìn tóbẹ́ẹ̀ tí eniyan kò lè dé ìsàlẹ̀ rẹ̀, yóo wá bá wọn jagun. Yóo ṣẹgun wọn, yóo sì pa wọ́n.

8 Òkú wọn yóo wà ní títì ìlú ńlá tí a ti kan Oluwa wọn mọ́ agbelebu. Àfiwé orúkọ rẹ̀ ni Sodomu ati Ijipti.

9 Àwọn eniyan láti inú gbogbo ẹ̀yà, ati gbogbo orílẹ̀-èdè yóo máa wo òkú wọn fún ọjọ́ mẹta ati ààbọ̀. Wọn kò ní jẹ́ kí wọ́n sin wọ́n.

10 Àwọn ọmọ aráyé yóo máa yọ̀ wọ́n, inú wọn yóo sì máa dùn. Wọn yóo máa fún ara wọn lẹ́bùn. Nítorí pé ìyọlẹ́nu ni àwọn akéde meji wọnyi jẹ́ fún àwọn tí wọn ń gbé orí ilẹ̀ ayé.

11 Lẹ́yìn ọjọ́ mẹta ati ààbọ̀ yìí, èémí ìyè láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun wọ inú wọn, ni wọ́n bá jí, wọn bá dìde dúró. Ẹ̀rù ba àwọn tí ó rí wọn gan-an.

12 Wọ́n wá gbọ́ ohùn líle láti ọ̀run wá tí ó sọ fún wọn pé, “Ẹ gòkè wá síhìn-ín.” Ni wọ́n bá gòkè lọ sọ́run ninu ìkùukùu, lójú àwọn ọ̀tá wọn.

13 Ilẹ̀ mì tìtì, ìdámẹ́wàá ìlú bá wó. Ẹẹdẹgbaarin (7,000) eniyan ni ó kú nígbà tí ilẹ̀ náà mì. Ẹ̀rù ba àwọn tí ó kù, wọ́n sì fi ògo fún Ọlọrun ọ̀run.

14 Ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú keji kọjá. Ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú kẹta fẹ́rẹ̀ dé.

Kàkàkí Keje

15 Angẹli keje fun kàkàkí rẹ̀, àwọn ohùn líle kan ní ọ̀run bá sọ pé, “Ìjọba ayé di ti Oluwa wa, ati ti Kristi rẹ̀. Yóo jọba lae ati laelae.”

16 Àwọn àgbààgbà mẹrinlelogun tí wọ́n jókòó lórí ìtẹ́ wọn níwájú Ọlọrun bá dojúbolẹ̀, wọ́n júbà Ọlọrun.

17 Wọ́n ní,

“A fi ìyìn fún ọ, Oluwa, Ọlọrun Olodumare,

ẹni tí ó wà, tí ó ti wà,

nítorí o ti gba agbára ńlá rẹ, o sì ń jọba.

18 Inú àwọn orílẹ̀-èdè ru,

ṣugbọn àkókò ibinu rẹ dé,

ó tó àkókò láti ṣe ìdájọ́ àwọn òkú,

ati láti fi èrè fún àwọn iranṣẹ rẹ, àwọn wolii, àwọn eniyan rẹ,

ati àwọn tí ó bẹ̀rù orúkọ rẹ, ìbáà ṣe àwọn mẹ̀kúnnù tabi àwọn eniyan ńláńlá.

Àkókò dé láti pa àwọn tí ó ń ba ayé jẹ́ run.”

19 Tẹmpili Ọlọrun ti ṣí sílẹ̀ ní ọ̀run, tí a fi lè rí àpótí majẹmu ninu rẹ̀. Mànàmáná wá bẹ̀rẹ̀ sí kọ, ààrá ń sán, ilẹ̀ ń mì tìtì; yìnyín sì bẹ̀rẹ̀ sí bọ́ sílẹ̀.

Categories
ÌFIHÀN

ÌFIHÀN 12

Obinrin kan ati Ẹranko Ewèlè

1 Mo wá rí àmì ńlá kan ní ọ̀run. Obinrin kan tí ó fi oòrùn ṣe aṣọ, tí òṣùpá wà lábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀. Ó dé adé tí ó ní ìràwọ̀ mejila.

2 Obinrin náà lóyún. Ó wá ń rọbí. Ó ń jẹ̀rora bí ó ti fẹ́ bímọ.

3 Mo wá tún rí àmì mìíràn ní ọ̀run: Ẹranko Ewèlè ńlá kan tí ó pupa bí iná, tí ó ní orí meje ati ìwo mẹ́wàá, ó dé adé meje.

4 Ó fi ìrù gbá ìdámẹ́ta àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run, wọ́n bá jábọ́ sórí ilẹ̀ ayé. Ẹranko Ewèlè yìí dúró níwájú obinrin tí ó fẹ́ bímọ yìí, ó fẹ́ gbé ọmọ náà jẹ bí ó bá ti bí i tán.

5 Obinrin yìí bí ọmọkunrin, tí yóo jọba lórí àwọn orílẹ̀-èdè pẹlu ọ̀pá irin. A bá já ọmọ náà gbà lọ sọ́dọ̀ Ọlọrun, níwájú ìtẹ́ rẹ̀.

6 Obinrin yìí bá sálọ sí aṣálẹ̀, níbìkan tí Ọlọrun ti pèsè sílẹ̀. Níbẹ̀ ni ó wà lábẹ́ ìtọ́jú fún ẹgbẹfa ọjọ́ ó lé ọgọta (1260).

7 Ogun wá bẹ́ sílẹ̀ ní ọ̀run. Mikaeli ati àwọn angẹli rẹ̀ ń bá Ẹranko Ewèlè náà jà. Ẹranko Ewèlè yìí ati àwọn angẹli rẹ̀ náà jà títí,

8 ṣugbọn kò lágbára tó láti ṣẹgun. Wọ́n bá lé òun ati àwọn angẹli rẹ̀ kúrò ní ọ̀run.

9 Wọ́n lé Ẹranko Ewèlè náà jáde–ejò àtijọ́ nì tí à ń pè ní Èṣù, tabi Satani tí ó ń tan àwọn tí ó ń gbé inú ayé jẹ. Wọ́n lé e jáde lọ sinu ayé, ati òun ati àwọn angẹli rẹ̀.

10 Mo wá gbọ́ ohùn líle kan ní ọ̀run tí ó sọ pé, “Àkókò ìgbàlà nìyí ati ti agbára, ati ìjọba ti Ọlọrun wa, ati àkókò àṣẹ Kristi rẹ̀. Nítorí a ti lé Olùfisùn àwọn onigbagbọ ara wa jáde, tí ó ń fi ẹjọ́ wọn sùn níwájú Ọlọrun wa tọ̀sán-tòru.

11 Wọ́n ti fi ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Aguntan ati ẹ̀rí ọ̀rọ̀ tí wọ́n jẹ́ ṣẹgun rẹ̀. Nítorí wọn kò ka ẹ̀mí wọn sí pé ó ṣe iyebíye jù kí wọ́n kú lọ.

12 Nítorí náà, ẹ máa yọ̀, ẹ̀yin ọ̀run ati ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé inú wọn. Ó ṣe fun yín, ayé, ati fún òkun! Nítorí Èṣù ti dé sáàrin yín. Inú rẹ̀ ń ru, nítorí ó mọ̀ pé ìgbà díẹ̀ ni ó kù fún òun.”

13 Nígbà tí Ẹranko Ewèlè náà rí i pé a lé òun jáde sinu ayé, ó bẹ̀rẹ̀ sí lé obinrin tí ó bí ọmọkunrin nnì kiri.

14 Ni a bá fún obinrin náà ní ìyẹ́ idì ńláńlá meji, kí ó lè fò lọ sí aṣálẹ̀ níbi tí wọ́n ti ń tọ́jú rẹ̀ fún ọdún mẹta ati oṣù mẹfa, tí ó fi bọ́ lọ́wọ́ ejò náà.

15 Ni ejò yìí bá tú omi jáde lẹ́nu bí odò, kí omi lè gbé obinrin náà lọ.

16 Ṣugbọn ilẹ̀ ran obinrin náà lọ́wọ́. Ilẹ̀ lanu, ó fa omi tí Ẹranko Ewèlè náà tu jáde lẹ́nu mu.

17 Inú wá bí Ẹranko Ewèlè yìí sí obinrin náà. Ó wá lọ gbógun ti àwọn ọmọ rẹ̀ yòókù, tí wọn ń pa àṣẹ Ọlọrun mọ́, tí wọn ń jẹ́rìí igbagbọ ninu Jesu.

18 Ó dúró lórí iyanrìn etí òkun.

Categories
ÌFIHÀN

ÌFIHÀN 13

Àwọn Ẹranko Meji

1 Mo wá rí ẹranko kan tí ń ti inú òkun jáde bọ̀. Ó ní ìwo mẹ́wàá ati orí meje. Adé mẹ́wàá wà lórí ìwo rẹ̀. Ó kọ orúkọ àfojúdi sára orí rẹ̀ kọ̀ọ̀kan.

2 Ẹranko náà tí mo rí dàbí àmọ̀tẹ́kùn. Ẹsẹ̀ rẹ̀ dàbí ti ìkookò. Ẹnu rẹ̀ dàbí ti kinniun. Ẹranko Ewèlè náà fún un ní agbára rẹ̀, ati ìtẹ́ rẹ̀ ati àṣẹ ńlá rẹ̀.

3 Ó dàbí ẹni pé wọ́n ti ṣá ọ̀kan ninu àwọn orí ẹranko náà lọ́gbẹ́. Ọgbẹ́ ọ̀hún tó ohun tí ó yẹ kí ó pa á ṣugbọn ó ti jinná. Gbogbo eniyan ni wọ́n ń tẹ̀lé ẹranko yìí tí wọ́n fi ń ṣe ìran wò.

4 Wọ́n ń júbà Ẹranko Ewèlè náà nítorí pé ó fi àṣẹ fún ẹranko yìí. Wọ́n sì ń júbà ẹranko náà, wọ́n ń sọ pé, “Ta ni ó dàbí ẹranko yìí? Ta ni ó tó bá a jà?”

5 A fún un ní ẹnu láti fi sọ̀rọ̀ tí ó ju ẹnu rẹ̀ lọ, ọ̀rọ̀ àfojúdi sí Ọlọrun. A fún un ní àṣẹ fún oṣù mejilelogoji.

6 Ó bá ya ẹnu, ó bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ àfojúdi sí Ọlọrun. Ó ń sọ ọ̀rọ̀ àfojúdi sí orúkọ Ọlọrun ati sí àgọ́ rẹ̀, ati sí àwọn tí wọ́n ń gbé ọ̀run.

7 A fún un ní agbára láti gbógun ti àwọn eniyan Ọlọrun ati láti ṣẹgun wọn. A tún fún un ní àṣẹ lórí gbogbo ẹ̀yà ati orílẹ̀-èdè ati oríṣìíríṣìí èdè ati gbogbo eniyan.

8 Gbogbo àwọn tí wọn ń gbé inú ayé tí a kò kọ orúkọ wọn sinu ìwé ìyè bá ń júbà rẹ̀. Láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé ni a kò ti kọ orúkọ wọn sinu ìwé Ọ̀dọ́ Aguntan tí a pa.

9 Ẹni tí ó bá ní etí, kí ó gbọ́!

10 Bí ẹnikẹ́ni bá níláti lọ sí ìgbèkùn, yóo lọ sí ìgbèkùn. Bí ẹnikẹ́ni bá fi idà pa eniyan, idà ni a óo fi pa òun náà. Níhìn-ín ni ìfaradà ati ìdúró ṣinṣin àwọn eniyan Ọlọrun yóo ti hàn.

11 Mo tún rí ẹranko mìíràn tí ó jáde láti inú ilẹ̀. Ó ní ìwo meji bíi ti Ọ̀dọ́ Aguntan. Ó ń sọ̀rọ̀ bíi ti Ẹranko Ewèlè.

12 Ó ń lo àṣẹ bíi ti ẹranko àkọ́kọ́, lójú ẹranko àkọ́kọ́ fúnrarẹ̀. Ó mú kí ayé ati àwọn tí ó ń gbé inú rẹ̀ júbà ẹranko àkọ́kọ́, tí ọgbẹ́ rẹ̀ ti san.

13 Ó ń ṣe iṣẹ́ abàmì ńláńlá. Ó mú kí iná sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá sí ayé lójú àwọn eniyan.

14 Ó fi iṣẹ́ abàmì tí a fi fún un láti ṣe níwájú ẹranko náà tan àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé jẹ. Ó sọ fún wọn pé kí wọ́n yá ère ẹranko tí a ti fi idà ṣá lọ́gbẹ́ tí ó tún yè.

15 A fún un ní agbára láti fi èémí sinu ère ẹranko náà, kí ère ẹranko náà lè fọhùn, kí ó lè pa àwọn tí kò bá júbà ère ẹranko náà.

16 Lẹ́yìn náà, gbogbo eniyan, ati àwọn mẹ̀kúnnù ati àwọn eniyan ńláńlá ati ọlọ́rọ̀ ati talaka, ati ẹrú ati òmìnira ni ẹranko yìí mú kí wọ́n ṣe àmì sí ọwọ́ ọ̀tún tabi iwájú wọn.

17 Kò sí ẹni tí ó lè ra ohunkohun tabi kí ó ta ohunkohun àfi ẹni tí ó bá ní àmì orúkọ ẹranko náà tabi ti iye orúkọ rẹ̀ lára.

18 Ohun tí ó gba ọgbọ́n nìyí. Ẹni tí ó bá ní òye ni ó lè mọ ìtumọ̀ àmì orúkọ ẹranko náà, nítorí pé bí orúkọ eniyan kan gan-an ni àmì yìí rí. Ìtumọ̀ iye àmì náà ni ọtalelẹgbẹta, ó lé mẹfa (666).

Categories
ÌFIHÀN

ÌFIHÀN 14

Orin Àwọn Ọ̀kẹ́ Meje Ó Lé Ẹgbaaji (144,000) Eniyan

1 Mo rí Ọ̀dọ́ Aguntan náà tí ó dúró lórí òkè Sioni, pẹlu àwọn ọ̀kẹ́ meje ó lé ẹgbaaji (144,000) eniyan tí a kọ orúkọ rẹ̀ ati orúkọ Baba rẹ̀ sí wọn níwájú.

2 Mo sì gbọ́ ohùn kan láti ọ̀run bí ìró ọpọlọpọ omi ati bí ìgbà tí ààrá líle bá ń sán. Ohùn tí mo gbọ́ ni ti àwọn oníhapu tí wọn ń lu hapu wọn.

3 Wọ́n ń kọrin titun kan níwájú ìtẹ́ náà ati níwájú àwọn ẹ̀dá alààyè mẹrin ati àwọn àgbààgbà mẹrinlelogun. Kò sí ẹni tí ó lè mọ orin náà àfi àwọn ọ̀kẹ́ meje ó lé ẹgbaaji (144,000) eniyan tí a ti rà pada ninu ayé.

4 Àwọn ni àwọn tí kò fi obinrin ba ara wọn jẹ́, nítorí wọn kò bá obinrin lòpọ̀ rí. Àwọn yìí ni wọ́n ń tẹ̀lé Ọ̀dọ́ Aguntan náà káàkiri ibi gbogbo tí ó bá ń lọ. Àwọn ni a ti rà pada láti inú ayé, wọ́n dàbí èso àkọ́so fún Ọlọrun ati fún Ọ̀dọ́ Aguntan.

5 Ọ̀rọ̀ èké kankan kò sí ní ẹnu wọn. Kò sí àléébù ninu ìgbé-ayé wọn.

Iṣẹ́ tí Àwọn Angẹli Mẹta Jẹ́

6 Mo tún rí angẹli mìíràn tí ń fò lágbedeméjì ọ̀run. Ó mú ìyìn rere ayérayé lọ́wọ́ láti kéde rẹ̀ fún àwọn tí wọ́n wà ninu ayé, ninu gbogbo ẹ̀yà ati gbogbo orílẹ̀-èdè.

7 Ó bá kígbe pé, “Ẹ bẹ̀rù Ọlọrun kí ẹ sì fi ògo fún un, nítorí àkókò ìdájọ́ rẹ̀ dé! Ẹ júbà ẹni tí ó dá ọ̀run ati ayé, òkun ati gbogbo orísun omi.”

8 Angẹli mìíràn tẹ̀lé ti àkọ́kọ́, ó ní, “Ó ti tú! Babiloni ìlú ńlá nnì ti tú! Ìlú tí ó fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ní ọtí àgbèrè rẹ̀ mu, tí ó mú ibinu Ọlọrun wá, ó ti tú!”

9 Angẹli kẹta wá tẹ̀lé wọn. Ó kígbe pé, “Bí ẹnikẹ́ni bá júbà ẹranko náà ati ère rẹ̀, tí ó gba àmì rẹ̀ siwaju rẹ̀ tabi sí ọwọ́ rẹ̀,

10 yóo mu ninu ògidì ọtí ibinu Ọlọrun, tí ó wà ninu ife ibinu rẹ̀. Olúwarẹ̀ yóo joró ninu iná àjóòkú níwájú àwọn angẹli mímọ́ ati Ọ̀dọ́ Aguntan.

11 Èéfín iná oró àwọn tí wọ́n bá júbà ẹranko náà ati ère rẹ̀, tí wọ́n gba àmì orúkọ rẹ̀, yóo máa rú títí lae. Kò ní rọlẹ̀ tọ̀sán-tòru.”

12 Èyí mú kí ó di dandan fún àwọn eniyan Ọlọrun, tí wọn ń pa àṣẹ Ọlọrun mọ́, tí wọ́n sì dúró ninu igbagbọ Jesu láti ní ìfaradà.

13 Mo gbọ́ ohùn kan láti ọ̀run wá tí ó sọ pé, “Kọ ọ́ sílẹ̀! Àwọn òkú tí wọ́n kú ninu Oluwa láti àkókò yìí lọ ṣe oríire.”

Ẹ̀mí jẹ́rìí sí i pé, “Bẹ́ẹ̀ ni dájúdájú, nítorí wọn yóo sinmi ninu làálàá wọn, nítorí iṣẹ́ wọn yóo máa tọ̀ wọ́n lẹ́yìn.”

Ìkórè Ayé

14 Mo wá rí ìkùukùu funfun. Ẹnìkan tí ó dàbí ọmọ eniyan jókòó lórí ìkùukùu náà. Ó dé adé wúrà. Ó mú dòjé tí ó mú lọ́wọ́.

15 Angẹli mìíràn jáde láti inú Tẹmpili wá, ó kígbe sí ẹni tí ó jókòó lórí ìkùukùu, pé, “Iṣẹ́ bẹ̀rẹ̀ fún dòjé rẹ; àkókò ìkórè tó: ilé ayé ti tó kórè.”

16 Ẹni tí ó jókòó lórí ìkùukùu náà bá ti dòjé rẹ̀ bọ ilé ayé, ni ó bá kórè ayé.

17 Angẹli mìíràn tún jáde wá láti inú Tẹmpili ní ọ̀run, tí òun náà tún mú dòjé mímú lọ́wọ́.

18 Angẹli mìíràn wá ti ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ ìrúbọ wá, òun ni ó ní àṣẹ lórí iná. Ó kígbe sí angẹli tí ó ní dòjé mímú pé, “Iṣẹ́ bẹ̀rẹ̀ fún dòjé mímú rẹ. Kó èso àwọn igi eléso ilé ayé jọ, nítorí pé wọ́n ti pọ́n.”

19 Ni angẹli tí ó ní dòjé náà bá ti dòjé rẹ̀ bọ inú ilé ayé, ó bá kó èso àjàrà ayé jọ, ó dà wọ́n sí ibi ìfúntí ibinu ńlá Ọlọrun.

20 Lẹ́yìn odi ìlú ni ìfúntí náà wà. Nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí tẹ èso ninu rẹ̀, ẹ̀jẹ̀ ni ó bẹ̀rẹ̀ sí yọ jáde láti inú ìfúntí náà. Jíjìn rẹ̀ mu ẹṣin dé ọrùn, ó sì gba ilẹ̀ lọ ní nǹkan bí igba ibùsọ̀.

Categories
ÌFIHÀN

ÌFIHÀN 15

Àwọn Angẹli tí Ó Mú Àjàkálẹ̀ Àrùn Ìkẹyìn Wá

1 Mo tún rí ohun abàmì mìíràn ní ọ̀run, ohun ńlá ati ohun ìyanu: àwọn angẹli meje tí àjàkálẹ̀ àrùn meje ti ìkẹyìn wà ní ìkáwọ́ wọn, nítorí pé àwọn ni wọ́n mú ibinu Ọlọrun wá sí òpin.

2 Mo tún rí ohun tí ó dàbí òkun dígí tí iná wà ninu rẹ̀. Àwọn kan dúró lẹ́bàá òkun dígí náà, àwọn tí wọ́n ti ṣẹgun ẹranko náà ati ère rẹ̀, ati iye orúkọ rẹ̀. Wọ́n mú hapu Ọlọrun lọ́wọ́,

3 wọ́n ń kọ orin Mose iranṣẹ Ọlọrun ati orin Ọ̀dọ́ Aguntan náà pé,

“Iṣẹ́ ńlá ati iṣẹ́ ìyanu ni iṣẹ́ rẹ,

Oluwa, Ọlọrun Olodumare.

Òdodo ati òtítọ́ ni àwọn iṣẹ́ ọnà rẹ,

Ọba àwọn orílẹ̀-èdè.

4 Ta ni kò ní bẹ̀rù rẹ, Oluwa?

Ta ni kò ní fi ògo fún orúkọ rẹ?

Nítorí ìwọ nìkan ni ó pé,

nítorí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yóo wá,

wọn yóo júbà níwájú rẹ,

nítorí òdodo rẹ farahàn gbangba.”

5 Lẹ́yìn èyí mo tún rí Tẹmpili tí ó ṣí sílẹ̀ ní ọ̀run. Àgọ́-Ẹ̀rí wà ninu rẹ̀.

6 Àwọn angẹli meje tí wọ́n ní àjàkálẹ̀ àrùn meje níkàáwọ́ jáde láti inú Tẹmpili náà wá, wọ́n wọ aṣọ funfun tí ó ń tàn bí ìmọ́lẹ̀. Wúrà ni wọ́n fi ṣe ìgbàyà wọn.

7 Ọ̀kan ninu àwọn ẹ̀dá alààyè náà fún ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu àwọn angẹli meje náà ní àwo wúrà kéékèèké kọ̀ọ̀kan, àwọn àwo wúrà yìí kún fún ibinu Ọlọrun, ẹni tí ó wà láàyè lae ati laelae.

8 Inú Tẹmpili wá kún fún èéfín ògo Ọlọrun ati ti agbára rẹ̀. Kò sí ẹni tí ó lè wọ inú Tẹmpili títí tí àwọn àjàkálẹ̀ àrùn meje ti àwọn angẹli meje náà fi parí.

Categories
ÌFIHÀN

ÌFIHÀN 16

Àwọn Àwo tí Ó Kún fún Ibinu Ọlọrun

1 Mo gbọ́ ohùn líle kan láti inú Tẹmpili tí ó sọ fún àwọn angẹli meje náà pé, “Ẹ lọ da àwọn àwo meje tí ó kún fún ibinu Ọlọrun sinu ayé.”

2 Angẹli kinni lọ, ó bá da ohun tí ó wà ninu àwo rẹ̀ sinu ayé. Ni egbò rírà tí ń rùn bá dà bo àwọn tí wọ́n ní àmì ẹranko náà ní ara, tí wọ́n sì ń júbà ère rẹ̀.

3 Angẹli keji da ohun tí ó wà ninu àwo rẹ̀ sinu òkun, ni òkun bá di ẹ̀jẹ̀, bí ẹ̀jẹ̀ ara òkú, gbogbo nǹkan ẹlẹ́mìí tí ó wà ninu òkun sì kú.

4 Angẹli kẹta da ohun tí ó wà ninu àwo rẹ̀ sinu odò ati sinu ìsun omi, ó bá di ẹ̀jẹ̀.

5 Mo wá gbọ́ ohùn angẹli tí omi wà ní ìkáwọ́ rẹ̀ tí ó sọ pé, “Olódodo ni ọ́ fún ìdájọ́ rẹ wọnyi, ìwọ tí ó wà, tí ó ti wà, ìwọ Ẹni Mímọ́!

6 Wọ́n ta ẹ̀jẹ̀ àwọn eniyan rẹ ati àwọn wolii rẹ sílẹ̀, nítorí náà o fún wọn ní ẹ̀jẹ̀ mu. Ohun tí ó yẹ wọ́n ni o fún wọn!”

7 Mo bá gbọ́ tí pẹpẹ ìrúbọ wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, Oluwa, Ọlọrun, Olodumare, òtítọ́ ati òdodo ni ìdájọ́ rẹ.”

8 Angẹli kẹrin da ohun tí ó wà ninu àwo rẹ̀ nù sórí oòrùn, a bá fún un lágbára láti máa jó eniyan bí iná.

9 Oòrùn bẹ̀rẹ̀ sí jó àwọn eniyan bí iná ńlá, wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí sọ ọ̀rọ̀ àfojúdi sí orúkọ Ọlọrun tí ó ní àṣẹ lórí àwọn àjàkálẹ̀ àrùn wọnyi, dípò kí wọ́n ronupiwada, kí wọ́n fi ògo fún un.

10 Angẹli karun-un da ohun tí ó wà ninu àwo rẹ̀ sórí ìtẹ́ ẹranko náà, ó bá sọ ìjọba rẹ̀ di òkùnkùn. Àwọn eniyan bẹ̀rẹ̀ sí gé ara wọn láhọ́n jẹ nítorí ìrora wọn,

11 wọn bá bẹ̀rẹ̀ sí sọ ọ̀rọ̀ àfojúdi sí Ọlọrun ọ̀run nítorí ìrora wọn ati nítorí egbò ara wọn, dípò kí wọ́n ronupiwada fún ohun tí wọ́n ti ṣe.

12 Angẹli kẹfa da ohun tí ó wà ninu àwo rẹ̀ sórí odò ńlá tí wọn ń pè ní Yufurate, ni omi rẹ̀ bá gbẹ láti fi ọ̀nà sílẹ̀ fún àwọn ọba tí ń bọ̀ láti ìhà ìlà oòrùn.

13 Mo wá rí àwọn ẹ̀mí burúkú mẹta kan, wọ́n dàbí ọ̀pọ̀lọ́ ní ẹnu Ẹranko Ewèlè náà, ati ní ẹnu wolii èké náà.

14 Ẹ̀mí Èṣù ni àwọn ẹ̀mí náà, wọ́n sì lè ṣe ohun abàmì. Wọ́n jáde lọ sọ́dọ̀ àwọn ọba ní gbogbo ayé, láti kó wọn jọ fún ogun ní ọjọ́ ńlá ti Ọlọrun alágbára jùlọ.

15 “Bí olè ni mò ń bọ̀. Ẹni tí ó bá ń ṣọ́nà ṣe oríire, tí olúwarẹ̀ wọ aṣọ rẹ̀, kí ó má baà sí ní ìhòòhò, kí ojú má baà tì í níwájú àwọn eniyan.”

16 Ó bá kó àwọn ọba wọnyi jọ sí ibìkan tí ń jẹ́ Amagedoni ní èdè Heberu.

17 Angẹli keje da ohun tí ó wà ninu àwo rẹ̀ sinu afẹ́fẹ́. Ẹnìkan bá fi ohùn líle sọ̀rọ̀ láti ibi ìtẹ́ tí ó wà ninu Tẹmpili, ó ní, “Ó ti parí!”

18 Ni mànàmáná bá bẹ̀rẹ̀ sí kọ, ààrá ń sán, ilẹ̀ ń mì tìtì, tóbẹ́ẹ̀ tí kò sí irú rẹ̀ rí láti ìgbà tí eniyan ti dé orí ilẹ̀ ayé.

19 Ìlú ńlá náà bá pín sí mẹta. Gbogbo ìlú àwọn orílẹ̀-èdè bá tú. Babiloni ìlú ńlá náà kò bọ́ lọ́wọ́ ìdájọ́ Ọlọrun, Ọlọrun jẹ́ kí ó mu ninu ìkorò ibinu rẹ̀.

20 Omi bo gbogbo àwọn erékùṣù, a kò sì rí ẹyọ òkè kan mọ́.

21 Yìnyín ńláńlá tí ó tóbi tó ọlọ ata wá bẹ̀rẹ̀ sí bọ́ lu eniyan láti ojú ọ̀run. Àwọn eniyan wá ń sọ ọ̀rọ̀ àfojúdi sí Ọlọrun nítorí ìparun tí yìnyín yìí ń fà, nítorí ó ń ṣe ọpọlọpọ ijamba.

Categories
ÌFIHÀN

ÌFIHÀN 17

Babiloni Ìlú Ńlá, Gbajúmọ̀ Àgbèrè

1 Ọ̀kan ninu àwọn angẹli meje tí wọ́n ní àwo meje náà tọ̀ mí wá, ó ní, “Wá kí n fi ìdájọ́ tí ń bọ̀ sórí gbajúmọ̀ aṣẹ́wó náà hàn ọ́, ìlú tí a kọ́ sójú ọpọlọpọ omi.

2 Àwọn ọba ayé ti ṣe àgbèrè pẹlu rẹ̀, àwọn tí ń gbé inú ayé ti mu ninu ọtí àgbèrè rẹ̀.”

3 Ẹ̀mí gbé mi, ni angẹli yìí bá gbé mi lọ sinu aṣálẹ̀. Níbẹ̀ ni mo ti rí obinrin tí ó gun ẹranko pupa kan, tí àwọn orúkọ àfojúdi kún ara rẹ̀. Ẹranko náà ní orí meje ati ìwo mẹ́wàá.

4 Aṣọ àlàárì ati aṣọ pupa ni obinrin náà wọ̀. Ó fi ọ̀ṣọ́ wúrà sára pẹlu oríṣìíríṣìí ìlẹ̀kẹ̀ olówó iyebíye. Ó mú ife wúrà lọ́wọ́, ife yìí kún fún ẹ̀gbin ati ohun ìbàjẹ́ àgbèrè rẹ̀.

5 Orúkọ àṣírí kan wà níwájú rẹ̀, ìtumọ̀ rẹ̀ ni: “Babiloni ìlú ńlá, ìyá àwọn àgbèrè ati oríṣìíríṣìí ohun ẹ̀gbin ayé.”

6 Mo wá rí obinrin náà tí ó ti mu ẹ̀jẹ̀ àwọn eniyan Ọlọrun ní àmuyó, pẹlu ẹ̀jẹ̀ àwọn tí wọ́n jẹ́rìí igbagbọ ninu Jesu.

Ìyanu ńlá ni ó jẹ́ fún mi nígbà tí mo rí obinrin náà.

7 Angẹli náà bi mí pé, “Kí ni ó yà ọ́ lẹ́nu? N óo sọ àṣírí obinrin náà fún ọ ati ti ẹranko tí ó gùn, tí ó ní orí meje ati ìwo mẹ́wàá.

8 Ẹranko tí o rí yìí ti wà láàyè nígbà kan rí, ṣugbọn kò sí láàyè mọ́ nisinsinyii. Ṣugbọn ó fẹ́rẹ̀ tó àkókò, tí yóo gòkè wá láti inú ọ̀gbun jíjìn, tí yóo wá lọ sí ibi ègbé. Nígbà tí wọ́n bá rí ẹranko náà ẹnu yóo ya àwọn tí ó ń gbé orí ilẹ̀ ayé, tí a kò kọ orúkọ wọn sinu ìwé ìyè láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé wá, nítorí ó ti wà láàyè, ṣugbọn kò sí láàyè nisinsinyii, ṣugbọn yóo tún pada yè.

9 “Ọ̀rọ̀ yìí gba ọgbọ́n. Orí meje tí ẹranko náà ní jẹ́ òkè meje tí obinrin náà jókòó lé lórí. Wọ́n tún jẹ́ ọba meje.

10 Marun-un ninu wọn ti kú. Ọ̀kan wà lórí oyè nisinsinyii. Ọ̀kan yòókù kò ì tíì jẹ. Nígbà tí ó bá jọba, àkókò díẹ̀ ni yóo ṣe lórí oyè.

11 Ẹranko tí ó ti wà láàyè rí, tí kò sí mọ́, ni ẹkẹjọ, ṣugbọn ó wà ninu àwọn meje tí ń lọ sinu ègbé.

12 “Àwọn ìwo mẹ́wàá tí o rí jẹ́ ọba mẹ́wàá. Ṣugbọn wọn kò ì tíì joyè. Wọn óo gba àṣẹ fún wakati kan, àwọn ati ẹranko náà ni yóo jọ lo àṣẹ náà.

13 Ète kanṣoṣo ni wọ́n ní. Wọn yóo fi agbára wọn ati àṣẹ wọn fún ẹranko náà.

14 Wọn yóo bá Ọ̀dọ́ Aguntan náà jagun, ṣugbọn Ọ̀dọ́ Aguntan náà yóo ṣẹgun wọn nítorí pé òun ni Oluwa àwọn oluwa ati Ọba àwọn ọba. Àwọn tí wọ́n wà pẹlu Ọ̀dọ́ Aguntan náà ninu ìjà ati ìṣẹ́gun náà ni àwọn tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́, tí a pè, tí a sì yàn.”

15 Ó tún wí fún mi pé, “Àwọn omi tí o rí níbi tí aṣẹ́wó náà ti jókòó ni àwọn eniyan ati gbogbo orílẹ̀-èdè.

16 Nígbà tí ó bá yá, àwọn ìwo mẹ́wàá tí o rí yìí ati ẹranko náà, yóo kórìíra aṣẹ́wó náà, wọn óo tú u sí ìhòòhò, wọn óo bá fi í sílẹ̀ ní ahoro. Wọn óo jẹ ẹran-ara rẹ̀, wọn óo bá dá iná sun ún títí yóo fi jóná ráúráú.

17 Nítorí Ọlọrun fi sí ọkàn wọn láti ní ète kan náà, pé àwọn yóo fi ìjọba àwọn fún ẹranko náà títí gbogbo ohun tí Ọlọrun ti sọ yóo fi ṣẹ.

18 “Obinrin tí o rí ni ìlú ńlá náà tí ó ń pàṣẹ lórí àwọn ọba ilẹ̀ ayé.”

Categories
ÌFIHÀN

ÌFIHÀN 18

Babiloni tú

1 Lẹ́yìn èyí mo tún rí angẹli tí ó ń ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ bọ̀. Ó ní àṣẹ ńlá. Gbogbo ayé mọ́lẹ̀ nítorí ẹwà ògo rẹ̀.

2 Ó wá kígbe pé, “Ó tú! Babiloni ìlú ńlá tú! Ó wá di ibi tí àwọn àǹjọ̀nnú ń gbé, tí ẹ̀mí Èṣù oríṣìíríṣìí ń pààrà, tí oríṣìíríṣìí ẹyẹkẹ́yẹ ń kiri.

3 Nítorí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ti mu àmuyó ninu ọtí àgbèrè rẹ̀, ọtí tí ó fa ibinu Ọlọrun. Àwọn ọba ilẹ̀ ayé ti ṣe àgbèrè pẹlu rẹ̀, àwọn oníṣòwò ilẹ̀ ayé ti di olówó nípa ìwà jayéjayé rẹ̀.”

4 Mo tún gbọ́ ohùn mìíràn láti ọ̀run tí ó sọ pé,

“Ẹ jáde kúrò ninu rẹ̀, ẹ̀yin eniyan mi,

kí ẹ má baà ní ìpín ninu ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀,

kí ẹ má baà fara gbá ninu ìjìyà rẹ̀.

5 Nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ga dé ọ̀run,

Ọlọrun kò gbàgbé àìṣedéédé rẹ̀.

6 Ṣe fún un bí òun náà ti ṣe fún eniyan.

Gbẹ̀san lára rẹ̀ ní ìlọ́po meji ìwà rẹ̀.

Ife tí ó fi ń bu ọtí fún eniyan ni

kí o fi bu ọtí tí ó le ní ìlọ́po meji fún òun alára.

7 Bí ó ti ṣe ń jẹ ọlá,

tí ó ń jẹ ayé tẹ́lẹ̀,

bẹ́ẹ̀ ni kí o fún un ní ìrora ati ìbànújẹ́.

Ó ń sọ ní ọkàn rẹ̀ pé,

‘Ọba orí ìtẹ́ ni mí,

èmi kì í ṣe opó,

ojú mi kò ní rí ìbànújẹ́.’

8 Nítorí èyí, ní ọjọ́ kan náà ni oríṣìíríṣìí òfò yóo dé bá a,

ati àjàkálẹ̀ àrùn, ati ọ̀fọ̀, ati ìyàn.

Iná yóo tún jó o ní àjórun,

nítorí alágbára ni Oluwa Ọlọrun tí ó ti ń ṣe ìdájọ́ fún un.”

9 Àwọn ọba ayé ati àwọn tí wọ́n ti bá a ṣe àgbèrè, tí wọ́n ti ń bá a jayé yóo sunkún, wọn óo ṣọ̀fọ̀ lé e lórí nígbà tí wọ́n bá rí èéfín iná tí ń jó o.

10 Wọn óo dúró ní òkèèrè nítorí ẹ̀rù tí yóo máa bà wọ́n nítorí ìrora rẹ̀. Wọn óo sọ pé,

“Ó ṣe! Ó ṣe fún ọ! Ìlú ńlá,

Babiloni ìlú alágbára!

Nítorí ní wakati kan ni ìparun dé bá ọ.”

11 Àwọn oníṣòwò ayé yóo sunkún, wọn yóo ṣọ̀fọ̀ lé e lórí, nítorí wọn kò rí ẹni ra ọjà wọn mọ́; àwọn nǹkan bíi:

12 Wúrà, fadaka, òkúta iyebíye, oríṣìíríṣìí ìlẹ̀kẹ̀, aṣọ funfun ati àlàárì, ati sányán ati aṣọ pupa; oríṣìíríṣìí pákó, ati àwọn ohun èèlò tí a fi eyín erin, igi iyebíye, idẹ, irin, ati òkúta ṣe;

13 oríṣìíríṣìí òróró ìkunra, turari ati òjíá, ọtí, òróró olifi, ọkà, ati àgbàdo, ẹṣin, kẹ̀kẹ́ ogun, ẹrú, àní ẹ̀mí eniyan.

14 Wọ́n ní, “Èso tí o fẹ́ràn kò sí mọ́, gbogbo ìgbé-ayé fàájì ati ti ìdẹ̀ra ti bọ́ lọ́wọ́ rẹ, o kò tún ní rí irú rẹ̀ mọ́.”

15 Àwọn oníṣòwò wọnyi, tí wọ́n ti di olówó ninu rẹ̀ yóo dúró ní òkèèrè nígbà tí ẹ̀rù bá ń bà wọ́n nítorí ìrora rẹ̀, wọn óo máa sunkún, wọn óo máa ṣọ̀fọ̀.

16 Wọn óo máa wí pé, “Ó ṣe! Ó ṣe fún ìlú ńlá náà! Ìlú tí ó wọ aṣọ funfun, ati aṣọ àlàárì ati aṣọ pupa. Ìlú tí wúrà pọ̀ níbẹ̀ ati òkúta iyebíye ati ìlẹ̀kẹ̀!

17 Ní wakati kan péré ni gbogbo ọrọ̀ rẹ̀ run!”

Nígbà náà ni gbogbo ọ̀gá àwọn awakọ̀ ojú omi, ati gbogbo àwọn tí ó ń wọ ọkọ̀ ati àwọn atukọ̀ ati àwọn tí iṣẹ́ wọn jẹ mọ́ ojú omi òkun lọ dúró ní òkèèrè.

18 Wọ́n ń kígbe sókè nígbà tí wọ́n rí èéfín iná tí ń jó ìlú náà. Wọ́n wá ń sọ pé, “Ìlú wo ni ó dàbí ìlú ńlá yìí?”

19 Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bu yẹ̀ẹ̀pẹ̀ sórí ara wọn, wọ́n ń sunkún, wọ́n ń ṣọ̀fọ̀. Wọ́n ní, “Ó ṣe! Ó ṣe fún ìlú ńlá náà, níbi tí gbogbo àwọn tí wọn ní ọkọ̀ lójú òkun ti di ọlọ́rọ̀ nípa ọrọ̀ rẹ̀, nítorí ní wakati kan ó ti di ahoro!

20 Ọ̀run, yọ̀ lórí rẹ̀! Ẹ yọ̀, ẹ̀yin eniyan Ọlọrun, ẹ̀yin aposteli, ati ẹ̀yin wolii, nítorí Ọlọrun ti ṣe ìdájọ́ fún un bí òun náà ti ṣe fún yín!”

21 Ọ̀kan ninu àwọn angẹli alágbára bá gbé òkúta tí ó tóbi bí ọlọ ògì, ó jù ú sinu òkun, ó ní, “Bẹ́ẹ̀ ni a óo fi tagbára-tagbára sọ Babiloni ìlú ńlá náà mọ́lẹ̀ tí a kò ní rí i mọ́.

22 A kò tún ní gbọ́ ohùn fèrè ati ti àwọn olórin tabi ti ohùn ìlù ati ti ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀ ninu rẹ mọ́. A kò ní tún rí àwọn oníṣọ̀nà fún iṣẹ́ ọnà kan ninu rẹ mọ́. A kò ní gbọ́ ìró ọlọ ninu rẹ mọ́.

23 Iná àtùpà kan kò ní tàn ninu rẹ mọ́, bẹ́ẹ̀ ni a kò ní gbọ́ ohùn ọkọ iyawo ati ti iyawo ninu rẹ mọ́. Nígbà kan rí àwọn oníṣòwò rẹ ni àwọn gbajúmọ̀ ninu ayé. O fi ìwà àjẹ́ tan gbogbo orílẹ̀-èdè jẹ.”

24 Ninu rẹ ni a ti rí ẹ̀jẹ̀ àwọn wolii ati ẹ̀jẹ̀ àwọn eniyan Ọlọrun, ati gbogbo àwọn ẹni tí wọ́n pa lórí ilẹ̀ ayé.

Categories
ÌFIHÀN

ÌFIHÀN 19

1 Lẹ́yìn èyí mo gbọ́ ohùn kan bí igbe ọ̀pọ̀ eniyan ní ọ̀run, tí ń sọ pé, “Haleluya! Ìgbàlà ati ògo ati agbára ni ti Ọlọrun wa.

2 Òtítọ́ ati òdodo ni ìdájọ́ rẹ̀. Nítorí ó ti dájọ́ fún gbajúmọ̀ aṣẹ́wó náà, tí ó fi àgbèrè rẹ̀ ba ayé jẹ́. Ó ti gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ àwọn iranṣẹ rẹ̀ lára rẹ̀.”

3 Wọ́n tún wí lẹẹkeji pé, “Haleluya! Èéfín rẹ̀ ń gòkè lae ati laelae.”

4 Àwọn àgbààgbà mẹrinlelogun náà ati àwọn ẹ̀dá alààyè mẹrin náà bá dojúbolẹ̀, wọ́n júbà Ọlọrun tí ó jókòó lórí ìtẹ́. Wọ́n ní, “Amin! Haleluya!”

Àsè Igbeyawo ti Ọ̀dọ́ Aguntan

5 Ẹnìkan fọhùn láti orí ìtẹ́ náà, ó ní, “Ẹ yin Ọlọrun wa, gbogbo ẹ̀yin ìran rẹ̀, ati gbogbo ẹ̀yin tí ẹ bẹ̀rù rẹ̀, ẹ̀yin mẹ̀kúnnù ati ẹ̀yin eniyan pataki.”

6 Mo tún gbọ́ ohùn kan bí ohùn ọ̀pọ̀ eniyan, ati bí ìró ọpọlọpọ omi, ati bí sísán ààrá líle, ohùn náà sọ pé, “Haleluya! Nítorí Oluwa Ọlọrun wa, Olodumare jọba.

7 Ẹ jẹ́ kí á yọ̀, kí inú wa dùn, ẹ jẹ́ kí á fi ògo fún un, nítorí ó tó àkókò igbeyawo Ọ̀dọ́ Aguntan náà. Iyawo rẹ̀ sì ti ṣe ara rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́ dè é.

8 A fún un ní aṣọ funfun tí ń dán, tí ó sì mọ́. Aṣọ funfun náà ni iṣẹ́ òdodo àwọn eniyan Ọlọrun.”

9 Ó sọ fún mi pé, “Kọ ọ́ sílẹ̀: àwọn tí a pè sí àsè igbeyawo ti Ọ̀dọ́ Aguntan náà ṣe oríire.” Ó tún sọ fún mi pé, “Òdodo ọ̀rọ̀ Ọlọrun ni ọ̀rọ̀ wọnyi.”

10 Ni mo bá dojúbolẹ̀ níwájú rẹ̀, mo júbà rẹ̀. Ó bá sọ fún mi pé, “Èèwọ̀! Má ṣe bẹ́ẹ̀! Iranṣẹ bí ìwọ ati àwọn arakunrin rẹ, tí wọ́n jẹ́rìí igbagbọ ninu Jesu, ni èmi náà. Ọlọrun ni kí o júbà.”

Nítorí ẹ̀mí tí ó mú kí eniyan jẹ́rìí igbagbọ ninu Jesu ni ẹ̀mí tí ó wà ninu wolii.

Ẹnìkan tí Ó Gun Ẹṣin Funfun

11 Mo rí ọ̀run tí ó ṣí sílẹ̀. Mo wá rí ẹṣin funfun kan. Orúkọ ẹni tí ó gùn ún ni Olódodo ati Olóòótọ́, nítorí pẹlu òdodo ni ó ń ṣe ìdájọ́, tí ó sì ń jagun.

12 Ojú rẹ̀ dàbí ọ̀wọ́ iná. Ó dé adé pupọ tí a kọ orúkọ sí, orúkọ tí ẹnikẹ́ni kò mọ̀ àfi òun alára.

13 Ó wọ ẹ̀wù tí a rẹ sinu ẹ̀jẹ̀. Orúkọ tí à ń pè é ni Ọ̀rọ̀ Ọlọrun.

14 Àwọn ọmọ-ogun ọ̀run ń tẹ̀lé e, wọ́n gun ẹṣin funfun. Aṣọ tí wọ́n wọ̀ funfun, ó sì mọ́.

15 Idà mímú yọ jáde ní ẹnu rẹ̀, tí yóo fi ṣẹgun àwọn orílẹ̀-èdè, nítorí òun ni yóo jọba lórí wọn pẹlu ọ̀pá irin. Òun ni yóo pọn ọtí ibinu ati ti ẹ̀san Ọlọrun Olodumare.

16 A kọ orúkọ kan sára ẹ̀wù ati sí itan rẹ̀ pé: “Ọba àwọn ọba ati Oluwa àwọn olúwa.”

17 Mo tún rí angẹli kan tí ó dúró ninu oòrùn, ó kígbe sí àwọn ẹyẹ tí ń fò lágbedeméjì ọ̀run pé, “Ẹ wá péjọ sí ibi àsè ńlá Ọlọrun,

18 kí ẹ lè jẹ ẹran-ara àwọn ọba ati ti àwọn ọ̀gágun, ati ti àwọn alágbára, ati ẹran ẹṣin ati ti àwọn tí wọ́n gùn wọ́n, ati ẹran-ara àwọn òmìnira ati ti ẹrú, ti àwọn mẹ̀kúnnù ati ti àwọn ọlọ́lá.”

19 Mo wá rí ẹranko náà ati àwọn ọba ilé ayé ati àwọn ọmọ-ogun wọn. Wọ́n péjọ láti bá ẹni tí ó gun ẹṣin funfun náà ati àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ jagun.

20 A mú ẹranko náà lẹ́rú, pẹlu wolii èké tí ó ń ṣe iṣẹ́ abàmì níwájú rẹ̀, tí ó ti tan àwọn tí wọ́n gba àmì ẹranko náà jẹ, ati àwọn tí wọ́n júbà ère rẹ̀. A wá gbé àwọn mejeeji láàyè, a sọ wọ́n sinu adágún iná tí a fi imí-ọjọ́ dá.

21 Wọ́n fi idà tí ó wà lẹ́nu ẹni tí ó gun ẹṣin funfun pa àwọn yòókù. Gbogbo àwọn ẹyẹ bá ń jẹ ẹran-ara wọn ní àjẹrankùn.