Categories
ÌFIHÀN

ÌFIHÀN Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ní àkókò tí wọn ń ṣe inúnibíni sí àwọn onigbagbọ nítorí gbígbà tí wọ́n gba Jesu bí Oluwa ni a kọ

Ìwé Ìfihàn Jesu fún Johanu.

Ohun tí ó jẹ ẹni tí ó kọ ìwé yìí lógún jùlọ ni láti fún àwọn olùka ìwé náà ní ìrètí, láti mú wọn lọ́kàn le, ati láti rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ ní àkókò ìjìyà ati inúnibíni.

Oríṣìíríṣìí ìran ati ìṣípayá ni ó tẹ̀lé ara wọn ninu ìwé yìí. Ó níláti jẹ́ pé èdè tí ẹni tí ó kọ ìwé yìí fi kọ ọ́ yé àwọn tí ó kọ ọ́ sí nígbà náà, ṣugbọn bí àdììtú ni ó rí fún gbogbo àwọn ẹlòmíràn. Bí àwọn olórin ti máa ń tẹnumọ́ ohun tí ó bá jẹ́ kókó ninu ọ̀rọ̀ orin wọn, bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ó kọ ìwé yìí ń tẹnumọ́ kókó ọ̀rọ̀ ìwé náà lemọ́lemọ́ ní oríṣìíríṣìí ọ̀nà, ninu oríṣìíríṣìí ìran tí ó rí. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èrò yàtọ̀ sí ara wọn lórí ìtumọ̀ ìwé yìí, ohun tí ó jẹ́ kókó tí ó wà ní ààrin gbùngbùn rẹ̀ hàn gedegbe. Òun sì ni pé nípasẹ̀ Kristi Oluwa, Ọlọrun yóo ṣẹgun gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ patapata níkẹyìn, tí ó fi kan Èṣù. Ọlọrun yóo sì fún àwọn eniyan rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ olódodo ní èrè. Èrè tí à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí ni ibukun ọ̀run titun ati ayé titun tí yóo dé lẹ́yìn tí Ọlọrun bá ti ṣẹgun patapata.

Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí

Ọ̀rọ̀ iṣaaju 1:1-8

Ìran tí ó ṣáájú ati ìwé sí àwọn ìjọ meje 1:9–3:22

Ìwé tí a fi èdìdì meje dì 4:1–8:1

Fèrè meje 8:2–11:19

Ẹranko Ewèlè ati àwọn ẹranko meji kan 12:1–13:18

Oríṣìíríṣìí ìran 14:1–15:8

Àwo meje tí ó kún fún ibinu Ọlọrun 16:1-21

Ìparun Babiloni ati ìṣẹ́gun ẹranko náà ati ti wolii èké ati ti Èṣù 17:1–20:10

Ìdájọ́ ìkẹyìn 20:11-15

Ọ̀run titun ati ayé titun, Jerusalẹmu titun 21:1–22:5

Ọ̀rọ̀ ìparí 22:6-21

Categories
ÌFIHÀN

ÌFIHÀN 1

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju ati Ìkíni

1 Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó níláti ṣẹlẹ̀ láìpẹ́ nìyí, tí Ọlọrun fún Jesu Kristi, pé kí ó fihan àwọn iranṣẹ rẹ̀. Jesu wá rán angẹli rẹ̀ sí Johanu, iranṣẹ rẹ̀, pé kí ó fi àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ náà hàn án.

2 Johanu sọ gbogbo nǹkan tí ó rí nípa ọ̀rọ̀ Ọlọrun ati ẹ̀rí Jesu Kristi.

3 Ẹni tí ó bá ń ka ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ yìí ati àwọn tí ó bá ń gbọ́, tí wọ́n sì ń ṣe àwọn ohun tí a kọ, ṣe oríire. Nítorí àkókò tí yóo ṣẹlẹ̀ súnmọ́ tòsí.

4 Èmi Johanu ni mo ranṣẹ sí ìjọ meje tí ó wà ní agbègbè Esia.

Kí oore-ọ̀fẹ́ ati alaafia wà pẹlu yín láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ó ti wà, tí ó ń bẹ, tí ó sì tún ń bọ̀ wá, ati láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹ̀mí meje tí wọ́n wà níwájú ìtẹ́ rẹ̀;

5 ati láti ọ̀dọ̀ Jesu Kristi, ẹlẹ́rìí òtítọ́, ẹnikinni tí ó jinde láti inú òkú ati aláṣẹ lórí àwọn ọba ilé ayé.

Ẹni tí ó fẹ́ràn wa, tí ó fi ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ dá wa nídè kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wa.

6 Ó sọ wá di ìjọba, ati alufaa Ọlọrun Baba rẹ̀. Tirẹ̀ ni ògo ati agbára lae ati laelae. Amin.

7 Wò ó! Ó ń bọ̀ ninu awọsanma, gbogbo eniyan ni yóo sì rí i. Àwọn tí wọ́n gún un lọ́kọ̀ náà yóo rí i. Gbogbo ẹ̀yà ilẹ̀ ayé yóo dárò nígbà tí wọ́n bá rí i. Amin! Àṣẹ!

8 “Èmi ni Alfa ati Omega, ìbẹ̀rẹ̀ ati òpin.” Oluwa Ọlọrun ló sọ bẹ́ẹ̀, ẹni tí ó ti wà, tí ń bẹ, tí ó sì tún ń bọ̀ wá, Olodumare.

Ìran Kristi

9 Èmi ni Johanu, arakunrin yín ati alábàápín pẹlu yín ninu ìpọ́njú tí ẹni tí ó bá tẹ̀lé Jesu níláti rí, ati ìfaradà tí ó níláti ní. Wọ́n jù mí sí ilẹ̀ kan tí ń jẹ́ Patimosi nítorí mo waasu ọ̀rọ̀ Ọlọrun, mo sì jẹ́rìí pé Jesu ni mo gbàgbọ́. Erékùṣù ni ilẹ̀ Patimosi, ó wà láàrin omi.

10 Nígbà tí ó di Ọjọ́ Oluwa, ni Ẹ̀mí bá gbé mi. Mo gbọ́ ohùn ńlá kan lẹ́yìn mi bí ìgbà tí fèrè bá ń dún,

11 ó ní, “Kọ ohun tí o bá rí sinu ìwé, kí o fi ranṣẹ sí àwọn ìjọ ní ìlú mejeeje wọnyi: Efesu ati Simana, Pẹgamu ati Tiatira, Sadi ati Filadẹfia ati Laodikia.”

12 Mo bá yipada láti wo ẹni tí ń bá mi sọ̀rọ̀. Bí mo ti yipada, mo rí ọ̀pá fìtílà wúrà meje.

13 Ní ààrin àwọn ọ̀pá fìtílà yìí ni ẹnìkan wà tí ó dàbí eniyan. Ó wọ ẹ̀wù tí ó balẹ̀ dé ilẹ̀. Ó fi ọ̀já wúrà gba àyà.

14 Irun orí rẹ̀ funfun gbòò bí ẹ̀gbọ̀n òwú. Ojú rẹ̀ ń kọ yànràn bí iná.

15 Ẹsẹ̀ rẹ̀ dàbí idẹ tí ń dán, tí alágbẹ̀dẹ ń dà ninu iná. Ohùn rẹ̀ dàbí híhó omi òkun.

16 Ó mú ìràwọ̀ meje lọ́wọ́ ọ̀tún rẹ̀. Idà olójú meji tí ó mú yọ jáde lẹ́nu rẹ̀. Ojú rẹ̀ mọ́lẹ̀ bí oòrùn ọ̀sán gangan.

17 Nígbà tí mo rí i, mo ṣubú lulẹ̀ lẹ́sẹ̀ rẹ̀ bí ẹni tí ó kú. Ó bá gbé ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ lé mi. Ó ní, “Má bẹ̀rù. Èmi ni ẹni kinni ati ẹni ìkẹyìn.

18 Èmi ni ẹni tí ó wà láàyè. Mo kú, ṣugbọn mo ti jí, mo sì wà láàyè lae ati laelae. Àwọn kọ́kọ́rọ́ ikú ati ti ipò òkú wà lọ́wọ́ mi.

19 Nítorí náà kọ àwọn ohun tí o rí sílẹ̀, ati àwọn ohun tí ó wà nisinsinyii ati àwọn ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ọ̀la.

20 Àṣírí ìràwọ̀ meje tí o rí ní ọwọ́ ọ̀tún mi, ati ti ọ̀pá fìtílà wúrà meje nìyí: ìràwọ̀ meje ni àwọn angẹli ìjọ meje. Ọ̀pá fìtílà meje ni àwọn ìjọ meje.

Categories
ÌFIHÀN

ÌFIHÀN 2

Iṣẹ́ sí Ìjọ Efesu

1 “Kọ ìwé yìí sí òjíṣẹ́ ìjọ Efesu:

“Ẹni tí ó di ìràwọ̀ meje mú ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, tí ó ń rìn láàrin àwọn ọ̀pá fìtílà wúrà meje wí báyìí pé,

2 Mo mọ iṣẹ́ rẹ, ati làálàá rẹ, ati ìfaradà rẹ. Mo mọ̀ pé o kò jẹ́ gba àwọn eniyan burúkú mọ́ra. O ti dán àwọn tí wọn ń pe ara wọn ní aposteli, tí wọn kì í ṣe aposteli wò, o ti rí i pé òpùrọ́ ni wọ́n.

3 O ní ìfaradà. O ti farada ìyà nítorí orúkọ mi, o kò sì jẹ́ kí àárẹ̀ mú ọ.

4 Ṣugbọn mo ní nǹkan wí sí ọ. O ti kọ ìfẹ́ tí o ní nígbà tí o kọ́kọ́ gbàgbọ́ sílẹ̀.

5 Nítorí náà, ranti bí o ti ga tó tẹ́lẹ̀ kí o tó ṣubú; ronupiwada, kí o sì ṣiṣẹ́ bíi ti àkọ́kọ́. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, mò ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ, bí o kò bá ronupiwada, n óo mú ọ̀pá fìtílà rẹ kúrò ní ipò rẹ̀.

6 Ṣugbọn ò ń ṣe kinní kan tí ó dára: o kórìíra iṣẹ́ àwọn Nikolaiti, tí èmi náà kórìíra.

7 “Ẹni tí ó bá ní etí, kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ.

“Ẹni tí ó bá ṣẹgun ni n óo fún ní àṣẹ láti jẹ ninu èso igi ìyè tí ó wà ninu ọgbà Ọlọrun.

Iṣẹ́ sí Ìjọ Simana

8 “Kọ ìwé yìí sí angẹli ìjọ Simana:

“Báyìí ni ẹni kinni ati ẹni ìkẹyìn wí, ẹni tí ó kú, tí ó tún wà láàyè:

9 Mo mọ̀ pé o ní ìṣòro; ati pé o ṣe aláìní, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọlọ́rọ̀ ni ọ́ ní ọ̀nà mìíràn. Mo mọ ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ tí àwọn tí wọn ń pe ara wọn ní Juu ń sọ, àwọn tí kì í sì í ṣe Juu; tí ó jẹ́ pé ilé ìpàdé Satani ni wọ́n.

10 Má bẹ̀rù ohunkohun tí ò ń bọ̀ wá jìyà. Èṣù yóo gbé ẹlòmíràn ninu yín jù sinu ẹ̀wọ̀n láti fi dán yín wò. Fún ọjọ́ mẹ́wàá ẹ óo ní ìṣòro pupọ. Ṣugbọn jẹ́ olóòótọ́ dé ojú ikú, Èmi yóo sì fún ọ ní adé ìyè.

11 “Ẹni tí ó bá ní etí, kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ.

“Ẹni tí ó bá ṣẹgun kò ní kú ikú keji.

Iṣẹ́ sí Ìjọ Pẹgamu

12 “Kọ ìwé yìí sí angẹli ìjọ Pẹgamu pé:

“Ẹni tí ó ní idà olójú meji tí ó mú ní:

13 Mo mọ ibi tí ò ń gbé, ibẹ̀ ni Satani tẹ́ ìtẹ́ rẹ̀ sí. Sibẹ o di orúkọ mi mú, o kò bọ́hùn ninu igbagbọ ní ọjọ́ tí wọ́n pa Antipasi ẹlẹ́rìí òtítọ́ mi ní ìlú yín níbi tí Satani fi ṣe ilé.

14 Ṣugbọn mo ní àwọn nǹkan díẹ̀ wí sí ọ. O ní àwọn kan láàrin ìjọ tí wọ́n gba ẹ̀kọ́ Balaamu, ẹni tí ó kọ́ Balaki láti fi ohun ìkọsẹ̀ siwaju àwọn ọmọ Israẹli, tí wọ́n fi ń jẹ oúnjẹ ìbọ̀rìṣà, tí wọ́n tún ń ṣe àgbèrè.

15 O tún ní àwọn kan tí àwọn náà gba ẹ̀kọ́ àwọn Nikolaiti.

16 Nítorí náà, ronupiwada. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́ n óo wá láìpẹ́, n óo sì fi idà tí ó wà lẹ́nu mi bá wọn jà.

17 “Ẹni tí ó bá ní etí, kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ.

“Ẹni tí ó bá ṣẹgun, Èmi óo fún un ní mana tí a ti fi pamọ́. N óo tún fún un ní òkúta funfun kan tí a ti kọ orúkọ titun sí lára. Ẹnikẹ́ni kò mọ orúkọ titun yìí àfi ẹni tí ó bá gba òkúta náà.

Iṣẹ́ sí Ìjọ Tiatira

18 “Kọ ìwé yìí sí ìjọ Tiatira pé:

“Ọmọ Ọlọrun, ẹni tí ojú rẹ̀ dàbí ọwọ́ iná, tí ẹsẹ̀ rẹ̀ ń dán bí idẹ.

19 Mo mọ iṣẹ́ rẹ. Mo mọ ìfẹ́ rẹ ati igbagbọ rẹ, mo mọ iṣẹ́ rere tí ò ń ṣe ati ìfaradà rẹ. Iṣẹ́ rẹ ti ìkẹyìn tilẹ̀ dára ju ti àkọ́kọ́ lọ.

20 Ṣugbọn mo ní nǹkan wí sí ọ. O gba obinrin tí wọn ń pè ní Jesebẹli láàyè. Ó ń pe ara rẹ̀ ní aríran, ó ń tan àwọn iranṣẹ mi jẹ, ó ń kọ́ wọn láti ṣe àgbèrè ati láti jẹ oúnjẹ ìbọ̀rìṣà.

21 Mo fún un ní àkókò kí ó ronupiwada, ṣugbọn kò fẹ́ ronupiwada kúrò ninu ìwà àgbèrè rẹ̀.

22 N óo dá a dùbúlẹ̀ àìsàn. Ìṣòro pupọ ni yóo bá àwọn tí wọ́n bá bá a ṣe àgbèrè, àfi bí wọ́n bá rí i pé iṣẹ́ burúkú ni ó ń ṣe, tí wọn kò sì bá a lọ́wọ́ ninu rẹ̀ mọ́.

23 N óo fi ikú pa àwọn ọmọ rẹ̀. Gbogbo àwọn ìjọ ni yóo wá mọ̀ pé Èmi ni Èmi máa ń wádìí ọkàn ati èrò ẹ̀dá, n óo sì fi èrè fún olukuluku yín gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀.

24 “Ṣugbọn ẹ̀yin yòókù ní Tiatira, ẹ̀yin tí ẹ kò gba ẹ̀kọ́ obinrin yìí, ẹ̀yin tí ẹ kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí wọn ń pè ní ohun ìjìnlẹ̀ Satani, n kò ní di ẹrù mìíràn rù yín mọ́.

25 Ṣugbọn ṣá, ẹ di ohun tí ẹ ní mú ṣinṣin títí n óo fi dé.

26-28 Ẹni tí ó bá ṣẹgun, tí ó forí tì í, tí ó ń ṣe iṣẹ́ mi títí dé òpin, òun ni n óo fún ní àṣẹ lórí àwọn orílẹ̀-èdè, ọ̀pá irin ni yóo fi jọba lórí wọn, bí ìkòkò amọ̀ ni yóo fọ́ wọn túútúú. Irú àṣẹ tí mo gbà lọ́dọ̀ Baba mi ni n óo fún un. N óo tún fún un ní ìràwọ̀ òwúrọ̀.

29 “Ẹni tí ó bá ní etí, kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ.

Categories
ÌFIHÀN

ÌFIHÀN 3

Iṣẹ́ sí Ìjọ Sadi

1 “Kọ ìwé yìí sí angẹli ìjọ Sadi:

“Ẹni tí ó ní Ẹ̀mí Ọlọrun meje ati ìràwọ̀ meje ní: Mo mọ iṣẹ́ rẹ. O kàn ní orúkọ pé o wà láàyè ni, òkú ni ọ́!

2 Jí lójú oorun! Fún àwọn ohun tí ó ṣẹ́kù ní okun, nítorí àwọn náà ń kú lọ. Nítorí n kò rí iṣẹ́ kan tí o ṣe parí níwájú Ọlọrun mi.

3 Nítorí náà, ranti ohun tí o ti gbà tí o sì ti gbọ́, ṣe é, kí o sì ronupiwada. Bí o kò bá jí lójú oorun, n óo dé bí olè, o kò sì ní mọ àkókò tí n óo dé bá ọ.

4 Ṣugbọn o ní àwọn díẹ̀ ninu ìjọ Sadi tí wọn kò fi èérí ba aṣọ wọn jẹ́. Wọn yóo bá mi kẹ́gbẹ́ ninu aṣọ funfun nítorí wọ́n yẹ.

5 Ẹni tí ó bá ṣẹgun ni a óo wọ̀ ní aṣọ funfun bẹ́ẹ̀. N kò ní pa orúkọ rẹ̀ rẹ́ kúrò ninu ìwé ìyè. N óo jẹ́wọ́ orúkọ rẹ̀ níwájú Baba mi ati níwájú àwọn angẹli rẹ̀.

6 “Ẹni tí ó bá ní etí, kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ.

Iṣẹ́ sí Ìjọ Filadẹfia

7 “Kọ ìwé yìí sí angẹli ìjọ Filadẹfia pé:

“Ẹni mímọ́ ati olóòótọ́ nì, ẹni tí kọ́kọ́rọ́ Dafidi ń bẹ ní ọwọ́ rẹ̀, tíí ṣí ìlẹ̀kùn tí ẹnikẹ́ni kò lè tì í, tíí sìí tìlẹ̀kùn tí ẹnikẹ́ni kò lè ṣí i, ó ní:

8 Mo mọ iṣẹ́ rẹ. Wò ó! Mo fi ìlẹ̀kùn kan tí ó ṣí sílẹ̀ siwaju rẹ, tí ẹnikẹ́ni kò lè tì. Mo mọ̀ pé agbára rẹ kéré, sibẹ o ti pa ọ̀rọ̀ mi mọ́. O kò sẹ́ orúkọ mi.

9 N óo fi àwọn kan láti inú ilé ìpàdé Satani lé ọ lọ́wọ́, àwọn òpùrọ́ tí wọn ń pe ara wọn ní Juu, bẹ́ẹ̀ sì ni wọn kì í ṣe Juu. N óo ṣe é tí wọn yóo fi wá sọ́dọ̀ rẹ, wọn yóo foríbalẹ̀ fún ọ, wọn yóo sì mọ̀ pé mo fẹ́ràn rẹ.

10 Nítorí o ti fi ìfaradà pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, Èmi náà yóo pa ọ́ mọ́ ní àkókò ìdánwò tí ń bọ̀ wá bá ayé, nígbà tí a óo dán gbogbo àwọn tí ó ń gbé inú ayé wò.

11 Mò ń bọ̀ kíákíá. Di ohun tí ń bẹ lọ́wọ́ rẹ mú ṣinṣin, kí ẹnikẹ́ni má baà gba adé rẹ.

12 Ẹni tí ó bá ṣẹgun ni n óo fi ṣe òpó ninu Tẹmpili Ọlọrun mi. Kò ní kúrò níbẹ̀ mọ́. N óo wá kọ orúkọ Ọlọrun mi ati orúkọ mi titun sí i lára, ati ti Jerusalẹmu titun, ìlú Ọlọrun mi, tí ń sọ̀kalẹ̀ bọ̀ láti ọ̀run, láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun mi.

13 “Ẹni tí ó bá ní etí kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń bá àwọn ìjọ sọ.

Iṣẹ́ sí Ìjọ Laodikia

14 “Kọ ìwé yìí sí angẹli ìjọ Laodikia pé:

“Ẹni tí ń jẹ́ Amin, olóòótọ́ ati ẹlẹ́rìí òdodo, alákòóso ẹ̀dá Ọlọrun ní

15 Mo mọ iṣẹ́ rẹ. Mo mọ̀ pé o kò gbóná, bẹ́ẹ̀ ni o kò tutù. Ninu kí o gbóná tabi kí o tutù, ó yẹ kí o ṣe ọ̀kan.

16 Nítorí pé o lọ́ wọ́ọ́rọ́wọ́ lásán, o kò gbóná, bẹ́ẹ̀ ni o kò tutù, n óo pọ̀ ọ́ jáde lẹ́nu mi.

17 Nítorí ò ń sọ pé: Mo lówó, mo lọ́rọ̀. Kò sí ohun tí mo fẹ́ tí n kò ní. O kò mọ̀ pé akúṣẹ̀ẹ́ tí eniyan ń káàánú ni ọ́, òtòṣì afọ́jú tí ó wà ní ìhòòhò.

18 Mo dá ọ nímọ̀ràn pé kí o ra wúrà tí wọ́n ti dà ninu iná lọ́wọ́ mi, kí o lè ní ọrọ̀, kí o ra aṣọ funfun kí o fi bora, kí ìtìjú ìhòòhò tí o wà má baà hàn, sì tún ra òògùn ojú, kí o fi sí ojú rẹ kí o lè ríran.

19 Àwọn tí mo bá fẹ́ràn ni mò ń bá wí, àwọn ni mò ń tọ́ sọ́nà. Nítorí náà ní ìtara, kí o sì ronupiwada.

20 Wò ó! Mo dúró ní ẹnu ọ̀nà, mò ń kan ìlẹ̀kùn. Bí ẹnikẹ́ni bá gbọ́ ohùn mi, tí ó ṣílẹ̀kùn, n óo wọlé tọ̀ ọ́ lọ, n óo bá a jẹun, òun náà yóo sì bá mi jẹun.

21 Ẹni tí ó bá ṣẹgun ni n óo jẹ́ kí ó jókòó tì mí lórí ìtẹ́ mi, gẹ́gẹ́ bí Èmi náà ti ṣẹgun, tí mo jókòó ti baba mi lórí ìtẹ́ rẹ̀.

22 “Ẹni tí ó bá ní etí, kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń bá àwọn ìjọ sọ.”

Categories
ÌFIHÀN

ÌFIHÀN 4

Ìsìn ní Ọ̀run

1 Lẹ́yìn èyí mo tún rí ìran mìíran. Mo rí ìlẹ̀kùn kan tí ó ṣí sílẹ̀ ní ọ̀run. Mo wá gbọ́ ohùn kan bíi ti àkọ́kọ́.

Tí ó dàbí ìgbà tí kàkàkí bá ń dún, tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀. Ó ní, “Gòkè wá níhìn-ín. N óo fi àwọn ohun tí ó níláti ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn èyí hàn ọ́.”

2 Lẹsẹkẹsẹ ni Ẹ̀mí bá gbé mi. Mo bá rí ìtẹ́ kan ní ọ̀run. Ẹnìkan jókòó lórí rẹ̀.

3 Ojú ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ náà dàbí òkúta iyebíye oríṣìí meji. Òṣùmàrè yí ìtẹ́ náà ká, ó ń tan ìmọ́lẹ̀ bí òkúta iyebíye.

4 Àwọn ìtẹ́ mẹrinlelogun ni wọ́n yí ìtẹ́ náà ká. Àwọn àgbààgbà mẹrinlelogun sì jókòó lórí ìtẹ́ mẹrinlelogun náà. Wọ́n wọ aṣọ funfun, wọ́n dé adé wúrà.

5 Mànàmáná ati ìró ààrá ń jáde láti ara ìtẹ́ tí ó wà láàrin. Ògùṣọ̀ meje tí iná wọn ń jó wà níwájú ìtẹ́ náà. Àwọn yìí ni Ẹ̀mí Ọlọrun meje.

6 Iwájú ìtẹ́ náà dàbí òkun dígí, ó rí bíi yìnyín, ó mọ́ gaara.

Àwọn ẹ̀dá alààyè mẹrin kan wà ní ààrin, wọ́n yí ìtẹ́ náà ká. Wọ́n ní ọpọlọpọ ojú níwájú ati lẹ́yìn.

7 Ekinni dàbí kinniun, ekeji dàbí akọ mààlúù, ojú ẹkẹta jọ ti eniyan, ẹkẹrin sì dàbí idì tí ó ń fò.

8 Ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu àwọn ẹ̀dá alààyè mẹrin náà ní apá mẹfa. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní ọpọlọpọ ojú. Wọn kì í sinmi tọ̀sán-tòru, wọ́n ń wí pé,

“Mímọ́! Mímọ́! Mímọ́!

Oluwa Ọlọrun Olodumare.

Ẹni tí ó ti wà, tí ó wà nisinsinyii,

tí ó sì ń bọ̀ wá.”

9 Nígbà tí àwọn ẹ̀dá alààyè mẹrin náà bá fi ògo, ọlá ati ìyìn fún ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́, ẹni tí ó wà láàyè lae ati laelae,

10 àwọn àgbààgbà mẹrinlelogun náà á dojúbolẹ̀ níwájú ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́, wọn a júbà ẹni tí ó wà láàyè lae ati laelae, wọn a fi adé wọn lélẹ̀ níwájú ìtẹ́ náà, wọ́n a máa wí pé,

11 “Oluwa Ọlọrun wa, ìwọ ni ó tọ́ sí láti gba ògo, ati ọlá ati agbára.

Nítorí ìwọ ni ó dá ohun gbogbo,

ati pé nípa ìfẹ́ rẹ ni wọ́n ṣe wà,

nípa rẹ ni a sì ṣe dá wọn.”

Categories
ÌFIHÀN

ÌFIHÀN 5

Ìwé Kíká ati Ọ̀dọ́ Aguntan

1 Lẹ́yìn náà, mo rí ìwé kan ní ọwọ́ ọ̀tún ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́: wọ́n kọ nǹkan sí i ninu ati lóde, wọ́n sì fi èdìdì meje dì í.

2 Mo sì rí angẹli alágbára kan tí ń ké pẹlu ohùn rara pé, “Ta ni ó yẹ láti ṣí ìwé náà, ati láti tú èdìdì rẹ̀?”

3 Kò sí ẹnikẹ́ni ní ọ̀run, tabi lórí ilẹ̀ tabi nísàlẹ̀ ilẹ̀ tí ó lè ṣí ìwé náà tabi tí ó lè wò ó.

4 Mo sunkún lọpọlọpọ nítorí kò sí ẹnikẹ́ni tí ó yẹ láti ṣí ìwé náà ati láti wò ó.

5 Ọ̀kan ninu àwọn àgbààgbà mẹrinlelogun yìí wá sọ fún mi pé, “Má sunkún mọ́! Wò ó! Kinniun ẹ̀yà Juda, ọmọ Dafidi, ti borí. Ó le ṣí ìwé náà ó sì le tú èdìdì meje tí a fi dì í.”

6 Mo bá rí Ọ̀dọ́ Aguntan tí ó dúró láàrin ìtẹ́ náà, àwọn ẹ̀dá alààyè mẹrin ati àwọn àgbààgbà mẹrinlelogun náà yí i ká. Ọ̀dọ́ Aguntan náà dàbí ẹni pé wọ́n ti pa á. Ìwo meje ni ó ní ati ojú meje. Àwọn ojú meje yìí ni Ẹ̀mí Ọlọrun meje tí Ọlọrun rán sí gbogbo orílẹ̀ ayé.

7 Ọ̀dọ́ Aguntan náà bá wá, ó sì gba ìwé náà ní ọwọ́ ọ̀tún ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́.

8 Nígbà tí ó gbà á, àwọn ẹ̀dá alààyè mẹrin ati àwọn mẹrinlelogun náà dojúbolẹ̀ níwájú Ọ̀dọ́ Aguntan yìí. Ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn mú hapu kọ̀ọ̀kan lọ́wọ́, ati àwo wúrà kéékèèké, tí ó kún fún turari. Turari yìí ni adura àwọn eniyan Ọlọrun, àwọn onigbagbọ.

9 Wọ́n wá ń kọ orin titun kan, pé,

“Ìwọ ni ó tọ́ sí láti gba ìwé náà,

ati láti tú èdìdì ara rẹ̀.

Nítorí wọ́n pa ọ́,

o sì ti fi ẹ̀jẹ̀ rẹ bá Ọlọrun ṣe ìràpadà eniyan,

láti inú gbogbo ẹ̀yà,

ati gbogbo eniyan ní gbogbo orílẹ̀-èdè.

10 O ti sọ wọ́n di ìjọba ti alufaa láti máa sin Ọlọrun wa.

Wọn yóo máa jọba ní ayé.”

11 Bí mo tí ń wò, mo gbọ́ ohùn ọpọlọpọ àwọn angẹli tí wọ́n yí ìtẹ́ náà ká ati àwọn ẹ̀dá alààyè ati àwọn àgbààgbà mẹrinlelogun. Àwọn angẹli náà pọ̀ pupọ: ẹgbẹẹgbẹrun ọ̀nà ẹgbẹẹgbẹrun àìmọye.

12 Wọ́n ń kígbe pé,

“Ọ̀dọ́ Aguntan tí a ti pa ni ó tọ́ sí

láti gba agbára, ọrọ̀, ọgbọ́n, ipá, ọlá, ògo ati ìyìn.”

13 Mo bá tún gbọ́ tí gbogbo ẹ̀dá tí ó wà lọ́run ati ní orílẹ̀ ayé, ati nísàlẹ̀ ilẹ̀, ati lórí òkun, ati ohun gbogbo tí ń bẹ ninu òkun, ń wí pé,

“Ìyìn, ọlá, ògo, ati agbára ni ti ẹni

tí ó jókòó lórí ìtẹ́ ati Ọ̀dọ́ Aguntan lae ati laelae.”

14 Àwọn ẹ̀dá alààyè mẹrin náà bá dáhùn pé, “Amin!” Àwọn àgbààgbà mẹrinlelogun sì dojúbolẹ̀, wọ́n júbà Ọlọrun.

Categories
ÌFIHÀN

ÌFIHÀN 6

Ọ̀dọ́ Aguntan Tú Èdìdì Mẹfa

1 Mo rí Ọ̀dọ́ Aguntan náà nígbà tí ó ń tú ọ̀kan ninu àwọn èdìdì meje náà. Mo gbọ́ tí ọ̀kan ninu àwọn ẹ̀dá alààyè mẹrin wí pẹlu ohùn tí ó dàbí ààrá, pé, “Wá!”

2 Mo bá rí ẹṣin funfun kan. Ẹni tí ó gùn ún mú ọrun ati ọfà lọ́wọ́. A fún un ní adé kan, ó bá jáde lọ bí aṣẹ́gun, ó ń ṣẹgun bí ó ti ń lọ.

3 Nígbà tí ó tú èdìdì keji, mo gbọ́ tí ẹ̀dá alààyè keji ní, “Wá!”

4 Ni ẹṣin mìíràn bá yọ jáde, òun pupa. A fi agbára fún ẹni tí ó gùn ún láti mú alaafia kúrò ní ayé, kí àwọn eniyan máa pa ara wọn. A wá fún un ní idà kan tí ó tóbi.

5 Nígbà tí ó tú èdìdì kẹta, mo gbọ́ tí ẹ̀dá alààyè kẹta ní, “Wá!” Mo rí ẹṣin dúdú kan. Ẹni tí ó gùn ún mú ìwọ̀n kan lọ́wọ́.

6 Mo wá gbọ́ nǹkankan tí ó dàbí ohùn láàrin àwọn ẹ̀dá alààyè mẹrin náà, ó ní, “Páànù ọkà bàbà kan fún owó fadaka kan. Páànù ọkà baali mẹta fún owó fadaka kan.Ṣugbọn o kò gbọdọ̀ fọwọ́ kan igi olifi ati ọtí waini.”

7 Nígbà tí ó tú èdìdì kẹrin, mo gbọ́ tí ẹ̀dá alààyè kẹrin ní, “Wá!”

8 Mo wá rí ẹṣin kan tí àwọ̀ rẹ̀ rí bíi ti ewéko tútù. Orúkọ ẹni tí ó gùn ún ni Ikú. Ẹni tí ó tẹ̀lé e ni Ipò-òkú. A fún wọn ní àṣẹ láti fi idà ati ìyàn ati àjàkálẹ̀ àrùn ati ẹranko burúkú pa idamẹrin ayé.

9 Nígbà tí ó tú èdìdì karun-un, ní abẹ́ pẹpẹ ìrúbọ, mo rí ọkàn àwọn tí a ti pa nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọrun ati nítorí ẹ̀rí tí wọ́n jẹ́.

10 Àwọn náà kígbe pé, “Oluwa mímọ́ ati olóòótọ́, nígbà wo ni ìwọ yóo ṣe ìdájọ́ fún àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé, tí ìwọ yóo gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ wa lára wọn?”

11 A wá fún ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní aṣọ funfun. A sọ fún wọn pé kí wọ́n sinmi díẹ̀ sí i títí iye àwọn iranṣẹ ẹlẹgbẹ́ wọn ati àwọn arakunrin wọn yóo fi pé, àwọn tí wọn yóo pa láìpẹ́ gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti pa àwọn ti iṣaaju.

12 Mo rí i nígbà tí ó tú èdìdì kẹfa pé ilẹ̀ mì tìtì. Oòrùn ṣókùnkùn, ó dàbí aṣọ dúdú. Òṣùpá wá dàbí ẹ̀jẹ̀.

13 Àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run já bọ́ sílẹ̀, bí ìgbà tí èso ọ̀pọ̀tọ́ bá já bọ́ lára igi rẹ̀ nígbà tí afẹ́fẹ́ líle bá fẹ́ lù ú.

14 Ojú ọ̀run fẹ́ lọ bí ìgbà tí eniyan bá ká ẹní. Gbogbo òkè ati erékùṣù ni wọ́n kúrò ní ipò wọn.

15 Àwọn ọba ayé, àwọn ọlọ́lá, àwọn ọ̀gágun, àwọn olówó, àwọn alágbára, ati gbogbo eniyan: ẹrú ati òmìnira, gbogbo wọn lọ sápamọ́ sinu ihò òkúta ati abẹ́ àpáta lára àwọn òkè.

16 Wọ́n ń sọ fún àwọn òkè ati àpáta pé, “Ẹ wó lù wá, kí ẹ pa wá mọ́ kúrò lójú ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ ati ibinu Ọ̀dọ́ Aguntan.

17 Nítorí ọjọ́ ńlá ibinu wọn dé; kò sì sí ẹni tí ó lè dúró.”

Categories
ÌFIHÀN

ÌFIHÀN 7

Ọ̀kẹ́ Meje Ó Lé Ẹgbaaji (144,000) Eniyan Israẹli

1 Lẹ́yìn èyí, mo rí àwọn angẹli mẹrin tí wọ́n dúró ní igun mẹrẹẹrin ayé, tí wọ́n di afẹ́fẹ́ mẹrẹẹrin ayé mú kí afẹ́fẹ́ má baà fẹ́ lórí ilẹ̀ ayé ati lórí òkun ati lára gbogbo igi.

2 Mo bá tún rí angẹli mìíràn tí ó gòkè wá láti ìhà ìlà oòrùn, tí ó mú èdìdì Ọlọrun alààyè lọ́wọ́. Ó kígbe lóhùn rara sí àwọn angẹli mẹrẹẹrin tí a fún ní agbára láti ṣe ayé ní jamba.

3 Ó ní, “Ẹ má ì tíì ṣe ilẹ̀ ayé ati òkun ati àwọn igi ní jamba títí tí a óo fi fi èdìdì sí àwọn iranṣẹ Ọlọrun wa níwájú.”

4 Mo gbọ́ iye àwọn tí a fi èdìdì sí níwájú, wọ́n jẹ́ ọ̀kẹ́ meje eniyan ó lé ẹgbaaji (144,000) láti inú gbogbo ẹ̀yà ọmọ Israẹli:

5-8 Láti inú ẹ̀yà Juda ẹgbaafa (12,000) ni a fi èdìdì sí níwájú, láti inú ẹ̀yà Reubẹni, ẹgbaafa (12,000), láti inú ẹ̀yà Gadi, ẹgbaafa (12,000); láti inú ẹ̀yà Aṣeri, ẹgbaafa (12,000), láti inú ẹ̀yà Nafutali, ẹgbaafa (12,000) láti inú ẹ̀yà Manase, ẹgbaafa (12,000), láti inú ẹ̀yà Simeoni, ẹgbaafa (12,000), láti inú ẹ̀yà Lefi, ẹgbaafa (12,000), láti inú ẹ̀yà Isakari, ẹgbaafa (12,000), láti inú ẹ̀yà Sebuluni ẹgbaafa (12,000), láti inú ẹ̀yà Josẹfu, ẹgbaafa (12,000), láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini, ẹgbaafa (12,000).

Àwọn Aṣẹ́gun láti Gbogbo Orílẹ̀-Èdè

9 Lẹ́yìn náà, mo rí ọ̀pọ̀ eniyan tí ẹnikẹ́ni kò lè kà láti gbogbo orílẹ̀-èdè ati ẹ̀yà, ati oríṣìíríṣìí èdè, wọ́n dúró níwájú ìtẹ́ náà ati níwájú Ọ̀dọ́ Aguntan. Wọ́n wọ aṣọ funfun. Wọ́n mú imọ̀ ọ̀pẹ lọ́wọ́.

10 Wọ́n wá ń kígbe pé, “Ti Ọlọrun wa tí ó jókòó lórí ìtẹ́, ati ti Ọ̀dọ́ Aguntan ni ìgbàlà.”

11 Gbogbo àwọn angẹli tí ó dúró yí ìtẹ́ náà ká, ati àwọn àgbààgbà mẹrinlelogun ati àwọn ẹ̀dá alààyè mẹrin dojúbolẹ̀ níwájú ìtẹ́ náà, wọ́n júbà Ọlọrun.

12 Wọ́n ń wí pé, “Amin! Ìyìn, ògo, ọgbọ́n, ọpẹ́, ọlá, agbára ati ipá ni fún Ọlọrun wa lae ati laelae. Amin!”

13 Ọ̀kan ninu àwọn àgbààgbà mẹrinlelogun yìí bi mí pé, “Ta ni àwọn wọnyi tí a wọ̀ ní aṣọ funfun? Níbo ni wọ́n sì ti wá?”

14 Mo bá dá a lóhùn pé, “Alàgbà, ìwọ ni ó mọ̀ wọ́n.”

Ó wá sọ fún mi pé, “Àwọn wọnyi ni wọ́n ti kọjá ninu ọpọlọpọ ìpọ́njú. Wọ́n ti fọ aṣọ wọn, wọ́n ti sọ wọ́n di funfun ninu ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Aguntan.

15 Nítorí èyí ni wọ́n ṣe wà níwájú ìtẹ́ Ọlọrun, tí wọn ń júbà tọ̀sán-tòru ninu Tẹmpili rẹ̀. Ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ náà yóo máa bá wọn gbé.

16 Ebi kò ní pa wọ́n mọ́, bẹ́ẹ̀ ni òùngbẹ kò ní gbẹ wọ́n mọ́. Oòrùn kò ní pa wọ́n mọ́, ooru kankan kò sì ní mú wọn mọ́.

17 Nítorí Ọ̀dọ́ Aguntan tí ó wà láàrin ìtẹ́ náà ni yóo máa ṣe olùtọ́jú wọn, yóo máa dà wọ́n lọ síbi ìsun omi ìyè.

Ọlọrun yóo wá nu gbogbo omijé kúrò ní ojú wọn.”

Categories
ÌFIHÀN

ÌFIHÀN 8

Ọ̀dọ́ Aguntan Tú Èdìdì Keje

1 Nígbà tí Ọ̀dọ́ Aguntan náà tú èdìdì keje, gbogbo ohun tí ó wà ní ọ̀run parọ́rọ́ fún bí ìdajì wakati kan.

2 Mo bá rí àwọn angẹli meje tí wọn máa ń dúró níwájú Ọlọrun, a fún wọn ní kàkàkí meje.

3 Angẹli mìíràn tún dé, ó dúró lẹ́bàá pẹpẹ ìrúbọ. Ó mú àwo turari tí wọ́n fi wúrà ṣe lọ́wọ́. A fún un ní turari pupọ kí ó fi rúbọ pẹlu adura gbogbo àwọn eniyan Ọlọrun lórí pẹpẹ ìrúbọ wúrà tí ó wà níwájú ìtẹ́ náà.

4 Èéfín turari ati adura àwọn eniyan Ọlọrun gòkè lọ siwaju Ọlọrun láti ọwọ́ angẹli náà.

5 Angẹli náà bá mú àwo turari yìí, ó bu iná láti orí pẹpẹ ìrúbọ kún inú rẹ̀, ó bá jù ú sí orí ilẹ̀ ayé. Ààrá bá bẹ̀rẹ̀ sí sán, mànàmáná ń kọ, ilẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí mì tìtì.

Àwọn Kàkàkí Mẹfa

6 Àwọn angẹli meje tí wọ́n mú kàkàkí meje lọ́wọ́ bá múra láti fun kàkàkí wọn.

7 Ekinni fun kàkàkí rẹ̀. Ni yìnyín ati iná pẹlu ẹ̀jẹ̀ bá tú dà sórí ilẹ̀ ayé. Ìdámẹ́ta ayé bá jóná, ati ìdámẹ́ta àwọn igi ati gbogbo koríko tútù.

8 Angẹli keji fun kàkàkí rẹ̀. Ni a bá ju nǹkankan tí ó dàbí òkè gíga tí ó ń jóná sinu òkun. Ó bá sọ ìdámẹ́ta òkun di ẹ̀jẹ̀.

9 Ìdámẹ́ta gbogbo ohun ẹlẹ́mìí tí ó wà ninu òkun ni wọ́n kú. Ìdámẹ́ta àwọn ọkọ̀ ojú òkun ni wọ́n sì fọ́ túútúú.

10 Angẹli kẹta fun kàkàkí rẹ̀. Ìràwọ̀ ńlá kan bá já bọ́ láti ọ̀run. Ó bẹ̀rẹ̀ sí jóná bí ògùṣọ̀. Ó bá já sinu ìdámẹ́ta àwọn odò ati ìsun omi.

11 Orúkọ ìràwọ̀ náà ni “Igi-kíkorò.” Ó mú kí ìdámẹ́ta omi korò, ọ̀pọ̀ eniyan ni ó sì kú nítorí oró tí ó wà ninu omi.

12 Angẹli kẹrin fun kàkàkí rẹ̀, ìdámẹ́ta oòrùn kò bá lè ràn mọ́; ati ìdámẹ́ta òṣùpá, ati ìdámẹ́ta àwọn ìràwọ̀. Ìdámẹ́ta wọn ṣókùnkùn, kò bá sí ìmọ́lẹ̀ fún ìdámẹ́ta ọ̀sán ati ìdámẹ́ta òru.

13 Mo tún rí ìran yìí. Mo gbọ́ tí idì kan tí ń fò ní agbede meji ọ̀run ń kígbe pé, “Ó ṣe! Ó ṣe! Ó ṣe fún gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé orí ilẹ̀ ayé nígbà tí kàkàkí tí àwọn angẹli mẹta yòókù fẹ́ fun bá dún!”

Categories
ÌFIHÀN

ÌFIHÀN 9

1 Angẹli karun-un wá fun kàkàkí rẹ̀, mo bá rí ìràwọ̀ kan tí ó ti ojú ọ̀run já bọ́ sí orí ilẹ̀ ayé. A fún ìràwọ̀ yìí ní kọ́kọ́rọ́ kànga tí ó jìn tóbẹ́ẹ̀ tí eniyan kò lè dé ìsàlẹ̀ rẹ̀.

2 Ó ṣí kànga náà, èéfín bá yọ láti inú kànga yìí, ó dàbí èéfín iná ìléru ńlá. Oòrùn ati ojú ọ̀run bá ṣókùnkùn nítorí èéfín tí ó jáde láti inú kànga náà.

3 Àwọn eṣú ti tú jáde láti inú èéfín náà, wọ́n lọ sí orí ilẹ̀ ayé. A fún wọn ní agbára bíi ti àkeekèé ayé.

4 A sọ fún wọn pé kí wọ́n má ṣe ohunkohun sí koríko orí ilẹ̀ tabi sí ewébẹ̀ tabi sí igi kan. Gbogbo àwọn eniyan tí kò bá ní èdìdì Ọlọrun ní iwájú wọn nìkan ni kí wọ́n ṣe léṣe.

5 A kò gbà pé kí wọ́n pa wọ́n, oró ni kí wọ́n dá wọn fún oṣù marun-un, kí wọ́n dá wọn lóró bí ìgbà tí àkeekèé bá ta eniyan.

6 Ní ọjọ́ náà àwọn eniyan yóo máa wá ikú ṣugbọn wọn kò ní kú; wọn yóo tọrọ ikú, ṣugbọn kò ní súnmọ́ wọn.

7 Àwọn eṣú wọnyi dàbí àwọn ẹṣin tí a dì ní gàárì láti lọ sójú ogun. Adé wà ní orí wọn tí ó dàbí adé wúrà. Ojú wọn dàbí ojú eniyan.

8 Irun wọn dàbí irun obinrin. Eyín wọn dàbí ti kinniun.

9 Wọ́n ní ìgbàyà tí ó dàbí ìgbàyà irin. Ìró ìyẹ́ wọn dàbí ìró ọpọlọpọ ọkọ̀ ẹlẹ́ṣin tí wọn ń sáré lọ sójú ogun.

10 Wọ́n ní ìrù bíi ti àkeekèé tí wọ́n fi lè ta eniyan. A fún wọn ní agbára ninu ìrù wọn láti ṣe eniyan léṣe fún oṣù marun-un.

11 Ọba wọn ni angẹli kànga tí ó jìn tóbẹ́ẹ̀ tí eniyan kò lè dé ìsàlẹ̀ rẹ̀. Orúkọ rẹ̀ ní èdè Heberu ni Abadoni; ní èdè Giriki orúkọ rẹ̀ ni Apolioni. Ìtumọ̀ rẹ̀ ni apanirun.

12 Ìṣòro kinni kọjá; ṣugbọn ó tún ku meji lẹ́yìn èyí.

13 Angẹli kẹfa fun kàkàkí rẹ̀. Mo bá gbọ́ ohùn kan láti ara àwọn ìwo tí ó wà lára pẹpẹ ìrúbọ wúrà tí ó wà níwájú Ọlọrun.

14 Ó sọ fún angẹli kẹfa tí ó mú kàkàkí lọ́wọ́ pé, “Dá àwọn angẹli mẹrin tí a ti dè ní odò ńlá Yufurate sílẹ̀.”

15 Ni wọ́n bá dá àwọn angẹli mẹrin náà sílẹ̀. A ti pèsè wọn sílẹ̀ fún wakati yìí, ní ọjọ́ yìí, ninu oṣù yìí, ní ọdún yìí pé kí wọ́n pa ìdámẹ́ta gbogbo eniyan.

16 Iye àwọn ọmọ-ogun ẹlẹ́ṣin jẹ́ ẹgbẹẹgbẹrun lọ́nà ọ̀kẹ́ mẹ́wàá (200,000,000). Mo gbọ́ iye wọn.

17 Bí àwọn ẹṣin ọ̀hún ati àwọn tí ó gùn wọ́n ti rí lójú mi, lójú ìran nìyí: wọ́n gba ọ̀já ìgbàyà tí ó pọ́n bí iná, ó dàbí àyìnrín, ó tún rí bí imí-ọjọ́. Orí àwọn ẹṣin náà dàbí orí kinniun. Wọ́n ń yọ iná, ati èéfín ati imí-ọjọ́ lẹ́nu.

18 Ohun ijamba mẹta yìí tí ó ń yọ jáde lẹ́nu wọn pa ìdá mẹta àwọn eniyan.

19 Agbára àwọn ẹṣin wọnyi wà ní ẹnu wọn ati ní ìrù wọn. Nítorí ìrù wọn dàbí ejò, wọ́n ní orí. Òun sì ni wọ́n fi ń ṣe àwọn eniyan léṣe.

20 Àwọn eniyan tí ó kù, tí wọn kò kú ninu àjàkálẹ̀ àrùn yìí kò ronupiwada. Wọn kò kọ iṣẹ́ ọwọ́ wọn tí wọn ń bọ sílẹ̀. Ṣugbọn wọ́n tún ń sin àwọn ẹ̀mí burúkú, ati oriṣa wúrà, ti fadaka, ti idẹ, ti òkúta, ati ti igi. Àwọn oriṣa tí kò lè ríran, wọn kò lè gbọ́ràn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò lè rìn.

21 Àwọn eniyan náà kò ronupiwada kúrò ninu ìwà ìpànìyàn, ìwà oṣó, ìwà àgbèrè ati ìwà olè wọn.