Categories
ÌṢE ÀWỌN APOSTELI

ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 20

Paulu lọ sí Masedonia ati Ilẹ̀ Giriki

1 Nígbà tí rògbòdìyàn náà kásẹ̀, Paulu ranṣẹ pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu. Ó gbà wọ́n níyànjú, ó sì dágbére fún wọn, ó bá lọ sí Masedonia.

2 Bí ó ti ń kọjá ní gbogbo agbègbè náà, bẹ́ẹ̀ ni ó ń gba àwọn eniyan níyànjú pẹlu ọ̀rọ̀ ìwúrí pupọ títí ó fi dé ilẹ̀ Giriki.

3 Ó ṣe oṣù mẹta níbẹ̀. Bí ó ti fẹ́ máa lọ sí Siria, ó rí i pé àwọn Juu ń dìtẹ̀ sí òun, ó bá gba Masedonia pada.

4 Sopata ọmọ Pirusi ará Beria bá a lọ. Bẹ́ẹ̀ náà ni Arisitakọsi ati Sekundu; ará Tẹsalonika ni wọ́n. Gaiyu ará Dabe ati Timoti náà bá a lọ, ati Tukikọsi ati Tirofimọsi; àwọn jẹ́ ará Esia.

5 Àwọn tí a wí yìí ṣiwaju wa lọ, wọ́n lọ dúró dè wá ní Tiroasi.

6 Àwa náà wá wọkọ̀ ojú omi ní Filipi lẹ́yìn Àjọ̀dún Àìwúkàrà, a bá wọn ní Tiroasi lọ́jọ́ karun-un. Ọjọ́ meje ni a lò níbẹ̀.

Paulu Bẹ Tiroasi Wò fún Ìgbà Ìkẹyìn

7 Ní alẹ́ ọjọ́ Satide, a péjọ láti jẹun; Paulu wá ń bá àwọn onigbagbọ sọ̀rọ̀. Ó ti wà lọ́kàn rẹ̀ pé lọ́jọ́ keji ni òun óo tún gbéra. Nítorí náà ó sọ̀rọ̀ títí dòru.

8 Àtùpà pọ̀ ninu iyàrá òkè níbi tí a péjọ sí.

9 Ọdọmọkunrin kan tí ó ń jẹ́ Yutiku jókòó lórí fèrèsé. Ó ti sùn lọ níbi tí Paulu gbé ń sọ̀rọ̀ lọ títí. Nígbà tí oorun wọ̀ ọ́ lára, ó ré bọ́ sílẹ̀ láti orí pẹ̀tẹ́ẹ̀sì kẹta. Nígbà tí wọn óo gbé e, ó ti kú.

10 Paulu bá sọ̀kalẹ̀, ó gbá a mú, ó dùbúlẹ̀ lé e lórí. Ó ní, “Ẹ má dààmú, nítorí ẹ̀mí rẹ̀ ṣì wà ninu rẹ̀.”

11 Nígbà tí ó pada sókè, ó gé burẹdi, ó jẹun. Ó wá ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ títí ó fi di àfẹ̀mọ́júmọ́. Ó bá jáde lọ.

12 Wọ́n mú ọmọ náà lọ sílé láàyè. Èyí sì tù wọ́n ninu lọpọlọpọ.

Ìrìn Àjò láti Tiroasi Dé Miletu

13 A bọ́ siwaju, a wọkọ̀ ojú omi lọ sí Asọsi. Níbẹ̀ ni a lérò pé Paulu yóo ti wá bá wa tí òun náà yóo sì wọkọ̀. Òun ló ṣe ètò bẹ́ẹ̀ nítorí ó fẹ́ fẹsẹ̀ rìn dé ibẹ̀.

14 Nígbà tí ó bá wa ní Asọsi, ó wọnú ọkọ̀ wa, a bá lọ sí Mitilene.

15 Ní ọjọ́ keji a kúrò níbẹ̀, a dé òdìkejì erékùṣù Kiosi. Ní ọjọ́ kẹta a dé Samosi. Ní ọjọ́ kẹrin a dé Miletu.

16 Nítorí Paulu ti pinnu láti wọkọ̀ kọjá Efesu, kí ó má baà pẹ́ pupọ ní Esia, nítorí ó ń dàníyàn pé bí ó bá ṣeéṣe, òun fẹ́ ṣe Àjọ̀dún Pẹntikọsti ní Jerusalẹmu.

Paulu Bá Àwọn Alàgbà Efesu Sọ̀rọ̀

17 Láti Miletu, Paulu ranṣẹ sí Efesu kí wọ́n lọ pe àwọn alàgbà ìjọ wá.

18 Nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ mọ̀ bí mo ti lo gbogbo àkókò mi láàrin yín láti ìgbà tí mo ti kọ́kọ́ dé ilẹ̀ Esia.

19 Ẹ mọ̀ bí mo ti fi ìrẹ̀lẹ̀ ati omi ojú sin Oluwa ní ọ̀nà gbogbo ninu àwọn ìṣòro tí mo fara dà nítorí ọ̀tẹ̀ tí àwọn Juu dì sí mi.

20 Ẹ mọ̀ pé n kò dánu dúró láti sọ ohunkohun fun yín tí yóo ṣe yín ní anfaani; mò ń kọ yín ní gbangba ati ninu ilé yín.

21 Mò ń tẹnu mọ́ ọn fún àwọn Juu ati àwọn Giriki pé kí wọn yipada sí Ọlọrun, kí wọn ní igbagbọ ninu Oluwa Jesu.

22 Nisinsinyii, gẹ́gẹ́ bí Ẹ̀mí ti darí mi, mò ń lọ sí Jerusalẹmu láì mọ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ sí mi níbẹ̀,

23 àfi pé láti ìlú dé ìlú ni Ẹ̀mí Mímọ́ ń fi àmì hàn mí pé ẹ̀wọ̀n ati ìyà ń dúró dè mí níbẹ̀.

24 Ṣugbọn n kò ka ẹ̀mí mi sí ohunkohun tí ó ní iye lórí fún ara mi. Ohun tí mò ń lépa ni láti parí iré ìje mi ati iṣẹ́ tí mo gbà lọ́wọ́ Oluwa mi Jesu, èyí ni pé kí n tẹnu mọ́ ìyìn rere oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun.

25 “Wàyí ò, èmi gan-an mọ̀ pé gbogbo ẹ̀yin tí mo ti ń waasu ìjọba Ọlọrun láàrin yín kò tún ní fi ojú kàn mí mọ́.

26 Nítorí náà mo sọ fun yín lónìí yìí pé bí ẹnikẹ́ni bá ṣègbé ninu yín, ẹ̀bi mi kọ́.

27 Nítorí n kò dánu dúró láti sọ gbogbo ohun tí Ọlọrun fẹ́ fun yín.

28 Ẹ ṣọ́ra yín, ẹ sì ṣọ́ agbo tí Ẹ̀mí Mímọ́ fi yín ṣe alabojuto lórí rẹ̀, kí ẹ máa bọ́ ìjọ Ọlọrun tí ó fi ẹ̀jẹ̀ Ọmọ rẹ̀ ṣe ní tirẹ̀.

29 Mo mọ̀ pé lẹ́yìn tí mo bá lọ, àwọn ẹhànnà ìkookò yóo wọ ààrin yín; wọn kò sì ní dá agbo sí.

30 Mo mọ̀ pé láàrin yín àwọn ẹlòmíràn yóo dìde tí wọn yóo fi irọ́ yí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu lọ́kàn pada láti tẹ̀lé wọn.

31 Nítorí náà, ẹ máa ṣọ́ra. Ẹ ranti pé fún ọdún mẹta, tọ̀sán-tòru ni n kò fi sinmi láti máa gba ẹnìkọ̀ọ̀kan yín níyànjú pẹlu omi lójú.

32 “Nisinsinyii, mo fi yín lé Ọlọrun lọ́wọ́ ati ọ̀rọ̀ oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ tí ó lè mu yín dàgbà, tí ó sì lè fun yín ní ogún pẹlu gbogbo àwọn tí a ti sọ di mímọ́.

33 N kò ṣe ojúkòkòrò owó tabi aṣọ tabi góòlù ẹnikẹ́ni.

34 Ẹ̀yin fúnra yín mọ̀ pé ọwọ́ ara mi yìí ni mo fi ṣiṣẹ́ tí mo fi ń gbọ́ bùkátà mi ati ti àwọn ẹlẹgbẹ́ mi.

35 Mo ti fihàn yín pé bẹ́ẹ̀ ni a níláti ṣiṣẹ́ láti ran àwọn aláìlera lọ́wọ́. Kí á máa ranti àwọn ọ̀rọ̀ Oluwa Jesu, nítorí òun fúnra rẹ̀ sọ pé, ‘Ayọ̀ pọ̀ ninu kí a máa fúnni ní nǹkan ju kí á máa gbà lọ.’ ”

36 Nígbà tí ó sọ báyìí tán, ó kúnlẹ̀ pẹlu gbogbo wọn, ó sì gbadura.

37 Gbogbo wọn bá ń sunkún. Wọ́n ń dì mọ́ ọn, wọ́n ń fi ẹnu kò ó lẹ́nu.

38 Èyí tí ó dùn wọ́n jù ni ọ̀rọ̀ tí ó sọ, pé wọn kò tún ní rí ojú òun mọ́. Wọ́n bá sìn ín lọ sí ìdíkọ̀.

Categories
ÌṢE ÀWỌN APOSTELI

ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 21

Ìrìn Àjò Paulu sí Jerusalẹmu

1 Nígbà tí a dágbére fún wọn tán, ọkọ̀ ṣí. A wá lọ tààrà sí Kosi. Ní ọjọ́ keji a dé Rodọsi. Láti ibẹ̀ a lọ sí Patara.

2 A rí ọkọ̀ ojú omi kan níbẹ̀ tí ó fẹ́ sọdá lọ sí Fonike. Ni a bá wọ̀ ọ́, ọkọ̀ bá ṣí.

3 Nígbà tí à ń wo Kipru lókèèrè, a gba ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún ibẹ̀ kọjá, a bá ń bá ọkọ̀ lọ sí ilẹ̀ Siria. A gúnlẹ̀ ní ìlú Tire, nítorí níbẹ̀ ni wọ́n fẹ́ já ẹrù ọkọ̀ sí.

4 A bá àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu kan níbẹ̀, a bá dúró tì wọ́n níbẹ̀ fún ọjọ́ meje. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu yìí sọ ohun tí Ẹ̀mí Mímọ́ fihàn wọ́n fún Paulu pé kí ó má lọ sí Jerusalẹmu.

5 Nígbà tí ọjọ́ tí a óo gbé níbẹ̀ pé, a gbéra láti máa bá ìrìn àjò wa lọ. Gbogbo wọn ati àwọn iyawo wọn ati àwọn ọmọ wọn sìn wá dé ẹ̀yìn odi. A bá kúnlẹ̀ lórí iyanrìn ní èbúté, a gbadura.

6 Ni a bá dágbére fún ara wa, a wọ inú ọkọ̀, àwọn sì pada lọ sí ilé wọn.

7 Láti Tire, a bá ń bá ìrìn àjò wa lọ títí a fi dé Tolemaisi. Níbẹ̀ a lọ kí àwọn onigbagbọ, a sì dúró lọ́dọ̀ wọn fún ọjọ́ kan.

8 Ní ọjọ́ keji, a gbéra, a lọ sí Kesaria. A wọ ilé Filipi, ajíyìnrere, ọ̀kan ninu àwọn meje tí àwọn ìjọ Jerusalẹmu yàn ní ijọ́sí. Lọ́dọ̀ rẹ̀ ni a dé sí.

9 Ó ní ọmọbinrin mẹrin. Wundia ni wọ́n, wọn a sì máa sọ àsọtẹ́lẹ̀.

10 A wà níbẹ̀ fún ọjọ́ pupọ. Nígbà tí à ń wí yìí ni Agabu aríran kan dé láti Judia.

11 Nígbà tí ó wá sọ́dọ̀ wa, ó mú ọ̀já ìgbànú Paulu, ó fi de ara rẹ̀ tọwọ́-tẹsẹ̀. Ó ní, “Ẹ gbọ́ bí Ẹ̀mí Mímọ́ ti wí: Báyìí ni àwọn Juu yóo di ọkunrin tí ó ni ọ̀já ìgbànú yìí ní Jerusalẹmu; wọn yóo sì fà á lé àwọn tí kì í ṣe Juu lọ́wọ́.”

12 Nígbà tí a gbọ́ ohun tí Agabu wí, àwa ati àwọn tí ó ń gbé ibẹ̀ bẹ Paulu pé kí ó má lọ sí Jerusalẹmu.

13 Ṣugbọn Paulu dáhùn pé, “Kí ló dé tí ẹ̀ ń sunkún, tí ẹ̀ ń mú ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn bá mi? Mo ti múra ẹ̀wọ̀n ati ikú pàápàá ní Jerusalẹmu nítorí orúkọ Oluwa Jesu.”

14 Nígbà tí a kò lè yí i lọ́kàn pada, a bá dákẹ́. A ní, “Ìfẹ́ Oluwa ni kí ó ṣẹ.”

15 Lẹ́yìn tí a gbé ọjọ́ bíi mélòó kan ni Kesaria, a palẹ̀ mọ́, a bá gbọ̀nà, ó di Jerusalẹmu.

16 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu ní Kesaria bá wa lọ. Wọ́n mú wa lọ sọ́dọ̀ ẹni tí a óo dé sí ilé rẹ̀, Minasoni ará Kipru kan báyìí tí ó ti di onigbagbọ tipẹ́tipẹ́.

Paulu Lọ Bẹ Jakọbu Wò

17 Nígbà tí a dé Jerusalẹmu, àwọn onigbagbọ gbà wá tayọ̀tayọ̀.

18 Ní ọjọ́ keji, Paulu bá lọ sọ́dọ̀ Jakọbu. Gbogbo àwọn àgbààgbà ni wọ́n pésẹ̀ sibẹ.

19 Nígbà tí Paulu kí wọn tán, ó ròyìn lẹ́sẹẹsẹ iṣẹ́ tí Ọlọrun lo òun láti ṣe láàrin àwọn tí kì í ṣe Juu.

20 Nígbà tí wọ́n gbọ́, wọ́n fi ògo fún Ọlọrun. Àwọn náà wá sọ fún un pé, “Wò ó ná, arakunrin, ṣé o mọ̀ pé ẹgbẹẹgbẹrun ni àwọn Juu tí ó gba Jesu gbọ́, tí gbogbo wọn sì ní ìtara sí Òfin Mose.

21 Wọ́n ń sọ nípa rẹ pé ò ń kọ́ gbogbo àwọn Juu tí ń gbé ààrin àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn pé kí wọ́n yapa kúrò ninu ìlànà Mose. Wọ́n ní o sọ pé kí wọn má kọ ọmọ wọn nílà; àtipé kí wọn má tẹ̀lé àṣà ìbílẹ̀ wọn mọ́.

22 Èwo ni ṣíṣe? Ó dájú pé wọn á gbọ́ pé o ti dé.

23 Bí a bá ti wí fún ọ ni kí o ṣe. Àwọn ọkunrin mẹrin kan wà lọ́dọ̀ wa tí wọ́n ti jẹ́jẹ̀ẹ́.

24 Mú wọn, kí o lọ bá wọn wẹ ẹ̀jẹ́ náà kúrò. San gbogbo owó tí wọn óo bá ná ati tìrẹ náà. Kí wọn wá fá orí wọn. Èyí yóo jẹ́ kí gbogbo eniyan mọ̀ pé kò sí òótọ́ ninu gbogbo nǹkan tí wọn ń sọ nípa rẹ. Wọn yóo mọ̀ pé Juu hánún-hánún ni ọ́ àtipé ò ń pa Òfin Mose mọ́.

25 Ní ti àwọn tí kì í ṣe Juu tí wọ́n gba Jesu gbọ́, a ti kọ ìwé sí wọn pé kí wọ́n yẹra fún oúnjẹ tí a ti fi rúbọ sí oriṣa, ati ẹ̀jẹ̀, ati ẹran tí a lọ́ lọ́rùn pa; kí wọn sì ṣọ́ra fún àgbèrè.”

26 Ní ọjọ́ keji, Paulu mú àwọn ọkunrin náà, ó ṣe ètò láti wẹ ẹ̀jẹ́ wọn kúrò, ati tirẹ̀ pẹlu. Ó wọ Tẹmpili lọ láti lọ ṣe ìfilọ̀ ọjọ́ tí àkókò ìwẹ̀nùmọ́ wọn yóo parí, tí òun yóo mú ọrẹ ti ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn wá.

Wọ́n Mú Paulu ninu Tẹmpili

27 Nígbà tí ọjọ́ meje náà fẹ́rẹ̀ pé, àwọn Juu láti Esia rí Paulu ninu Tẹmpili. Wọ́n bá ké ìbòòsí láàrin gbogbo èrò, wọ́n sì dọwọ́ bo Paulu,

28 wọ́n ń kígbe pé, “Ẹ̀yin eniyan Israẹli, ẹ gbani o! Ọkunrin tí ń kọ́ àwọn eniyan nígbà gbogbo láti lòdì sí orílẹ̀-èdè wa ati Òfin Mose ati ilé yìí nìyí. Ó tún mú àwọn Giriki wọ inú Tẹmpili; ó wá sọ ibi mímọ́ yìí di àìmọ́.”

29 Wọ́n sọ báyìí nítorí pé wọ́n ti kọ́kọ́ rí Tirofimọsi ará Efesu pẹlu Paulu láàrin ìlú, wọ́n wá ṣebí Paulu mú un wọ inú Tẹmpili ni.

30 Gbogbo ìlú bá dàrú. Àwọn eniyan ń rọ́ lọ sọ́dọ̀ Paulu. Wọ́n bá mú un, wọ́n wọ́ ọ jáde kúrò ninu Tẹmpili. Lẹsẹkẹsẹ wọ́n bá ti gbogbo ìlẹ̀kùn.

31 Wọ́n fẹ́ pa á ni ìròyìn bá kan ọ̀gá àwọn ọmọ-ogun pé gbogbo Jerusalẹmu ti dàrú.

32 Lójú kan náà ó bá mú àwọn ọmọ-ogun pẹlu àwọn balogun ọ̀rún tí ó wà lábẹ́ rẹ̀, ó sáré lọ bá wọn. Nígbà tí àwọn èrò rí ọ̀gágun ati àwọn ọmọ-ogun, wọ́n dáwọ́ dúró, wọn kò lu Paulu mọ́.

33 Ọ̀gágun bá súnmọ́ Paulu, ó mú un, ó bá pàṣẹ pé kí wọ́n fi ẹ̀wọ̀n meji dè é. Ó wá wádìí ẹni tí ó jẹ́ ati ohun tí ó ṣe.

34 Àwọn kan ninu èrò ń sọ nǹkankan; àwọn mìíràn ń sọ nǹkan mìíràn. Nígbà tí ọ̀gágun náà kò lè mọ òtítọ́ ọ̀rọ̀ náà nítorí ariwo èrò, ó pàṣẹ pé kí wọ́n mú Paulu lọ sí àgọ́ àwọn ọmọ-ogun.

35 Nígbà tí wọ́n dé àtẹ̀gùn ilé, gbígbé ni àwọn ọmọ-ogun níláti gbé Paulu wọlé nítorí ojú àwọn èrò ti ranko.

36 Ogunlọ́gọ̀ àwọn eniyan ni wọ́n ń tẹ̀lé wọn, tí wọn ń kígbe pé, “Ẹ pa á!”

Paulu Rojọ́

37 Bí wọ́n ti fẹ́ mú Paulu wọ inú àgọ́ ọmọ-ogun, ó sọ fún ọ̀gágun pé, “Ṣé kò léèwọ̀ bí mo bá bá ọ sọ nǹkankan?”

Ọ̀gágun wá bi í léèrè pé, “O gbọ́ èdè Giriki?

38 Ìyẹn ni pé kì í ṣe ìwọ ni ará Ijipti tí ó dá rúkèrúdò sílẹ̀ láìpẹ́ yìí, tí ó kó ẹgbaaji (4000) àwọn agúnbẹ lẹ́yìn lọ sí aṣálẹ̀?”

39 Paulu dáhùn ó ní, “Juu ni mí, ará Tasu ní ilẹ̀ Silisia. Ọmọ ìlú tí ó lókìkí ni mí. Gbà mí láàyè kí n bá àwọn eniyan sọ̀rọ̀.”

40 Nígbà tí ó gbà fún un, Paulu dúró lórí àtẹ̀gùn, ó gbọ́wọ́ sókè kí àwọn eniyan lè dákẹ́. Nígbà tí wọ́n dákẹ́, ó bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ ní èdè àwọn Heberu.

Categories
ÌṢE ÀWỌN APOSTELI

ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 22

1 Ó ní “Ẹ̀yin ará mi ati ẹ̀yin baba wa, ẹ fetí sí ẹjọ́ tí mo ní í rò fun yín nisinsinyii.”

2 Nígbà tí wọ́n gbọ́ tí ó ń bá wọn sọ̀rọ̀ ní èdè Heberu, wọ́n pa lọ́lọ́. Paulu bá bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀, ó ní,

3 “Juu ni mí, Tasu ní ilẹ̀ Silisia la gbé bí mi. Ní ìlú yìí ni a gbé tọ́ mi dàgbà. Ilé-ìwé Gamalieli ni mo lọ, ó sì kọ́ mi dáradára nípa Òfin ìbílẹ̀ wa. Mo ní ìtara fún Ọlọrun gẹ́gẹ́ bí gbogbo yín ti ní lónìí.

4 Mo ṣe inúnibíni sí ọ̀nà ẹ̀sìn yìí. Gbogbo àwọn tí ń tẹ̀lé Jesu ni mò ń lé kiri: ẹni tí mo bá sì bá ninu wọn pípa ni. Èmi a mú wọn, èmi a dè wọ́n, wọn a sì sọ wọ́n sẹ́wọ̀n, atọkunrin atobinrin wọn.

5 Olórí Alufaa pàápàá lè jẹ́rìí mi, ati gbogbo àwọn àgbààgbà. Ọwọ́ wọn ni mo ti gba ìwé lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn arakunrin wa ní Damasku. Mo lọ sibẹ láti de àwọn ẹlẹ́sìn yìí kí n sì mú wọn wá sí Jerusalẹmu láti jẹ wọ́n níyà.

Paulu Sọ Bí Ó Ṣe Di Onigbagbọ

6 “Bí mo ti ń lọ, tí mo súnmọ́ Damasku, lójijì, ní ọ̀sán gangan, ìmọ́lẹ̀ ńlá kan láti ọ̀run tàn yí mi ká.

7 Mo bá ṣubú lulẹ̀. Mo wá gbọ́ ohùn ẹnìkan tí ó ń sọ fún mi pé, ‘Saulu! Saulu! Kí ló dé tí o fi ń ṣe inúnibíni sí mi?’

8 Mo wá dáhùn, mo ní, ‘Ta ni ọ́, Oluwa?’ Ó bá sọ fún mi pé, ‘Èmi ni Jesu ará Nasarẹti, ẹni tí ò ń ṣe inúnibíni sí.’

9 Àwọn tí wọ́n wà pẹlu mi rí ìmọ́lẹ̀ náà, ṣugbọn wọn kò gbọ́ ohùn ẹni tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀.

10 Mo bá bèèrè pé, ‘Kí ni kí n ṣe Oluwa?’ Oluwa bá dá mi lóhùn pé, ‘Dìde kí o máa lọ sí Damasku. Níbẹ̀ a óo sọ fún ọ gbogbo nǹkan tí a ti ṣètò fún ọ láti ṣe.’

11 N kò lè ríran mọ́ nítorí ìmọ́lẹ̀ náà mọ́lẹ̀ pupọ. Àwọn ẹni tí ó wà pẹlu mi bá fà mí lọ́wọ́ lọ sí Damasku.

12 “Lẹ́yìn náà ni ọkunrin kan tí ń jẹ́ Anania dé. Ó jẹ́ olùfọkànsìn nípa ti Òfin Mose; gbogbo àwọn ẹni tí ń gbé Judia ni wọ́n sì jẹ́rìí rere nípa rẹ̀.

13 Ó dúró tì mí, ó ní, ‘Saulu arakunrin, lajú!’ Lẹsẹkẹsẹ ojú mi là, mo bá gbójú sókè wò ó.

14 Ó bá sọ fún mi pé, Ọlọrun àwọn baba wa ni ó yàn mí tẹ́lẹ̀ pé kí n mọ ìfẹ́ rẹ̀, kí n fojú rí iranṣẹ Olódodo rẹ̀, kí n sì gbọ́ ohùn òun pàápàá;

15 kí n lè ṣe ẹlẹ́rìí rẹ̀ níwájú gbogbo eniyan nípa ohun tí mo rí, ati ohun tí mo gbọ́.

16 Ó wá bèèrè pé, kí ni mo tún ń fẹ́ nisinsinyii? Ó ní kí n dìde, kí n ṣe ìrìbọmi, kí n wẹ ẹ̀ṣẹ̀ mi nù, kí n pe orúkọ Oluwa.

A rán Paulu sí Àwọn tí Kì í Ṣe Juu

17 “Nígbà tí mo ti pada sí Jerusalẹmu, bí mo ti ń gbadura ninu Tẹmpili, mo rí ìran kan.

18 Mo rí Oluwa tí ó ń sọ fún mi pé, ‘Jáde kúrò ní Jerusalẹmu kíákíá, nítorí wọn kò ní gba ẹ̀rí tí ò ń jẹ́ nípa mi.’

19 Mo dáhùn, mo ní, ‘Oluwa, àwọn gan-an mọ̀ pé èmi ni mo máa ń sọ àwọn tí ó bá gbà ọ́ gbọ́ sẹ́wọ̀n, tí mo sì máa ń nà wọ́n káàkiri láti ilé ìpàdé kan dé ekeji.

20 Wọ́n mọ̀ pé nígbà tí wọ́n pa Stefanu, ẹlẹ́rìí rẹ, bí mo ti dúró nìyí, tí mò ń kan sáárá sí àwọn tí ó pa á tí mò ń ṣọ́ aṣọ wọn.’

21 Ṣugbọn Oluwa sọ fún mi pé, ‘Bọ́ sọ́nà, nítorí n óo rán ọ lọ sí ọ̀nà jíjìn, sí ọ̀dọ̀ àwọn tí kì í ṣe Juu.’ ”

Paulu ati Ọ̀gágun Ọmọ Ìbílẹ̀ Romu

22 Àwọn eniyan fetí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀ títí gbolohun yìí fi jáde. Nígbà tí wọ́n gbọ́ gbolohun yìí, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kígbe pé, “Ẹ pa irú ẹni bẹ́ẹ̀ rẹ́ kúrò láyé! Kò yẹ kí ó wà láàyè!”

23 Wọ́n bá ń pariwo, wọ́n ń fi aṣọ wọn, wọ́n sì ń da ìyẹ̀pẹ̀ sókè.

24 Ni ọ̀gágun bá pàṣẹ pé kí wọ́n mú Paulu wọ àgọ́ ọmọ-ogun lọ. Ó ní kí wọn nà án kí wọn fi wádìí ọ̀rọ̀ lẹ́nu rẹ̀, kí ó lè mọ ìdí tí àwọn eniyan ṣe ń pariwo lé e lórí bẹ́ẹ̀.

25 Bí wọ́n ti ń dè é mọ́lẹ̀ láti máa nà án, Paulu bi balogun ọ̀rún tí ó dúró pé, “Ẹ̀tọ́ wo ni ẹ níláti na ọmọ-ìbílẹ̀ Romu láì tíì dá a lẹ́jọ́?”

26 Nígbà tí balogun ọ̀rún gbọ́, ó lọ sọ́dọ̀ ọ̀gágun, ó bi í pé, “Kí lẹ fẹ́ ṣe? Ọmọ ìbílẹ̀ Romu ni ọkunrin yìí o!”

27 Ní ọ̀gágun bá lọ bi Paulu, ó ní, “Wí kí n gbọ́, ọmọ-ìbílẹ̀ Romu ni ọ́?”

Paulu dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni.”

28 Ọ̀gágun náà bá dá a lóhùn pé, “Ọpọlọpọ owó ni mo ná kí n tó di ọmọ-ìbílẹ̀ Romu.”

Ṣugbọn Paulu ní, “Ní tèmi o, wọ́n bí mi bẹ́ẹ̀ ni.”

29 Lẹsẹkẹsẹ ni àwọn tí wọ́n fẹ́ wádìí ọ̀rọ̀ lẹ́nu rẹ̀ bá bìlà. Ẹ̀rù wá ba ọ̀gágun náà nígbà tí ó mọ̀ pé ọmọ-ìbílẹ̀ Romu ni Paulu, àtipé òun ti fi ẹ̀wọ̀n dè é.

Paulu Lọ siwaju Àwọn Ìgbìmọ̀ Juu

30 Lọ́jọ́ keji, ọ̀gágun náà tú Paulu sílẹ̀. Ó fẹ́ mọ òtítọ́ ẹ̀sùn tí àwọn Juu mú wá nípa rẹ̀. Ó bá pàṣẹ pé kí àwọn olórí alufaa ati gbogbo ìgbìmọ̀ péjọ. Ó bá mú Paulu lọ siwaju wọn.

Categories
ÌṢE ÀWỌN APOSTELI

ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 23

1 Paulu kọjú sí àwọn ìgbìmọ̀, ó ní, “Ẹ̀yin ará, ní gbogbo ìgbé-ayé mi, ọkàn mí mọ́ níwájú Ọlọrun títí di òní.”

2 Bí ó ti sọ báyìí, bẹ́ẹ̀ ni Anania Olórí Alufaa sọ fún àwọn tí ó dúró ti Paulu pé kí wọ́n gbá a lẹ́nu.

3 Paulu wá sọ fún un pé, “Ọlọrun yóo lù ọ́. Ìwọ ògiri tí wọ́n kùn lẹ́fun lásán yìí! O jókòó sibẹ, ò ń dá mi lẹ́jọ́ lórí Òfin, sibẹ o pa Òfin tì, o ní kí wọ́n lù mí.”

4 Àwọn tí wọ́n dúró níbẹ̀ bá ní, “Olórí Alufaa Ọlọrun ni ò ń bú bẹ́ẹ̀?”

5 Paulu dáhùn pé, “Ará, n kò mọ̀ pé Olórí Alufaa ni. Nítorí ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ sọ̀rọ̀ burúkú sí aláṣẹ àwọn eniyan rẹ.’ ”

6 Nígbà tí Paulu mọ̀ pé àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Sadusi ni apá kan ninu àwọn tí wọ́n wà ninu ìgbìmọ̀, àtipé àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Farisi ni àwọn mìíràn, ó kígbe pé, “Ẹ̀yin ará, Farisi ni mí. Farisi ni àwọn òbí mi. Nítorí ìrètí wa pé àwọn òkú yóo jí dìde ni wọ́n ṣe mú mi wá dáhùn ẹjọ́.”

7 Nígbà tí ó sọ báyìí, ìyapa bẹ́ sílẹ̀ láàrin àwọn Farisi ati àwọn Sadusi, ìgbìmọ̀ bá pín sí meji.

8 Nítorí àwọn Sadusi sọ pé kò sí ajinde, bẹ́ẹ̀ ni kò sí angẹli tabi àwọn ẹ̀mí; ṣugbọn àwọn Farisi gbà pé mẹtẹẹta wà.

9 Ni ariwo ńlá bá bẹ́ sílẹ̀. Àwọn amòfin kan ninu àwọn Farisi dìde, wọ́n tẹnu mọ́ ọn pé, “Àwa kò rí nǹkan burúkú tí ọkunrin yìí ṣe. Bí ó bá jẹ́ pé ẹ̀mí ni ó sọ̀rọ̀ fún un ńkọ́? Tabi angẹli?”

10 Nígbà tí àríyànjiyàn náà pọ̀ pupọ, ẹ̀rù ba ọ̀gágun pé kí wọn má baà fa Paulu ya. Ó bá pàṣẹ fún àwọn ọmọ-ogun kí wọn wá fi agbára mú Paulu kúrò láàrin wọn, kí wọn mú un wọnú àgọ́ àwọn ọmọ-ogun lọ.

11 Ní òru ọjọ́ keji, Oluwa dúró lẹ́bàá Paulu, ó ní, “Ṣe ọkàn rẹ gírí. Gẹ́gẹ́ bí o ti jẹ́rìí iṣẹ́ mi ní Jerusalẹmu, bẹ́ẹ̀ ni o níláti jẹ́rìí nípa mi ní Romu náà.”

Àwọn Juu Dìtẹ̀ láti Pa Paulu

12 Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, àwọn Juu péjọ pọ̀ láti dìtẹ̀ sí Paulu. Wọ́n búra pé àwọn kò ní jẹun, bẹ́ẹ̀ ni àwọn kò ní mu omi títí àwọn yóo fi pa Paulu.

13 Àwọn tí wọ́n dìtẹ̀ yìí ju bí ogoji lọ.

14 Wọ́n lọ sọ́dọ̀ àwọn olórí alufaa ati àwọn àgbààgbà, wọ́n ní, “A ti jẹ́jẹ̀ẹ́, a sì ti búra pé a kò ní fẹnu kan nǹkankan títí a óo fi pa Paulu.

15 A fẹ́ kí ẹ̀yin ati gbogbo wa ranṣẹ sí ọ̀gá àwọn ọmọ-ogun pé kí ó fi Paulu ranṣẹ sí yín nítorí ẹ fẹ́ wádìí ọ̀rọ̀ rẹ̀ fínnífínní. Ní tiwa, a óo ti múra sílẹ̀ láti pa á kí ó tó dé ọ̀dọ̀ yín.”

16 Ṣugbọn ọmọ arabinrin Paulu kan gbọ́ nípa ète yìí. Ó bá lọ sí àgọ́ àwọn ọmọ-ogun, ó lọ ròyìn fún Paulu.

17 Paulu wá pe ọ̀kan ninu àwọn balogun ọ̀rún, ó ní, “Mú ọdọmọkunrin yìí lọ sọ́dọ̀ ọ̀gágun, nítorí ó ní ọ̀rọ̀ kan láti sọ fún un.”

18 Balogun ọ̀rún náà bá mú un lọ sọ́dọ̀ ọ̀gágun. Ó ní, “Ẹlẹ́wọ̀n tí ń jẹ́ Paulu ni ó pè mí, tí ó ní kí n mú ọdọmọkunrin yìí wá sọ́dọ̀ yín nítorí ó ní ọ̀rọ̀ kan láti sọ fun yín.”

19 Ọ̀gágun náà bá fà á lọ́wọ́, ó mú un lọ sí kọ̀rọ̀. Ó wá bi í pé, “Kí ni o ní sọ fún mi?”

20 Ọdọmọkunrin náà wá dáhùn pé, “Àwọn Juu ti fohùn ṣọ̀kan láti bẹ̀ yín pé kí ẹ mú Paulu wá siwaju ìgbìmọ̀ lọ́la kí àwọn le wádìí ọ̀rọ̀ rẹ̀ ní fínnífínní.

21 Ẹ má gbà fún wọn. Nítorí àwọn kan ninu wọn yóo dènà dè é, wọ́n ju ogoji lọ. Wọ́n ti búra pé àwọn kò ní jẹun, bẹ́ẹ̀ ni àwọn kò ní mu omi títí àwọn yóo fi pa Paulu. Bí a ti ń sọ̀rọ̀ yìí, wọ́n ti múra tán. Ohun tí wọn ń retí ni kí ẹ ṣe ìlérí pé ẹ óo fi Paulu ranṣẹ sí ìgbìmọ̀.”

22 Ọ̀gágun bá ní kí ọdọmọkunrin náà máa lọ. Ó kìlọ̀ fún un pé kí ó má sọ fún ẹnikẹ́ni pé ó ti fi ọ̀rọ̀ yìí tó òun létí.

A fi Paulu Ranṣẹ sí Fẹliksi Gomina

23 Ọ̀gágun náà bá pe meji ninu àwọn balogun ọ̀rún tí ó wà lábẹ́ rẹ̀, ó ní, “Ẹ lọ mú igba ọmọ-ogun ati aadọrin ẹlẹ́ṣin ati igba ọmọ-ogun tí ó ní ọ̀kọ̀. Ẹ óo lọ sí Kesaria. Kí ẹ múra láti lọ ní agogo mẹsan-an alẹ́.

24 Ẹ tọ́jú àwọn ẹṣin tí Paulu yóo gùn, kí ẹ sìn ín dé ọ̀dọ̀ Fẹliksi gomina ní alaafia.”

25 Ó wá kọ ìwé lé wọn lọ́wọ́. Ìwé náà lọ báyìí:

26 “Gomina ọlọ́lá jùlọ, Fẹliksi, èmi Kilaudiu Lisia ki yín.

27 Àwọn Juu mú ọkunrin yìí, wọ́n fẹ́ pa á. Mo gbà á lọ́wọ́ wọn pẹlu àwọn ọmọ-ogun mi nítorí mo gbọ́ pé ọmọ-ìbílẹ̀ Romu ni.

28 Mo fẹ́ mọ ìdí tí wọ́n ṣe fi ẹ̀sùn kàn án. Mo bá mú un lọ sí iwájú ìgbìmọ̀ wọn.

29 Mo rí i pé ẹ̀sùn tí wọ́n ní jẹ mọ́ ọ̀rọ̀ òfin wọn; kò ṣe ohunkohun tí a lè fi sọ pé kí á pa á tabi kí á jù ú sí ẹ̀wọ̀n.

30 Nígbà tí ìròyìn kàn mí pé àwọn kan láàrin àwọn Juu ti dìtẹ̀ sí ọkunrin yìí, mo bá fi í ranṣẹ si yín. Mo ti sọ fún àwọn tí ó fi ẹ̀sùn kàn án pé kí wọ́n wá sọ ohun tí wọ́n ní sí i níwájú yín.”

31 Àwọn ọmọ-ogun ṣe bí a ti pàṣẹ fún wọn. Wọ́n mú Paulu lóru lọ sí ìlú Antipatiri.

32 Ní ọjọ́ keji wọ́n fi Paulu sílẹ̀ pẹlu àwọn ọmọ-ogun ẹlẹ́ṣin, wọ́n pada sí àgọ́ wọn.

33 Àwọn ọmọ-ogun ẹlẹ́ṣin bá a lọ sí Kesaria. Wọ́n fún gomina ní ìwé, wọ́n sì fa Paulu lé e lọ́wọ́.

34 Gomina ka ìwé náà. Ó wá wádìí pé apá ibo ni Paulu ti wá. Wọ́n sọ fún un pé ní agbègbè Silisia ni.

35 Ó bá sọ fún un pé, “N óo gbọ́ ẹjọ́ rẹ nígbà tí àwọn tí ó fi ẹjọ́ rẹ sùn náà bá dé.” Ó bá pàṣẹ pé kí wọ́n máa ṣọ́ Paulu ní ààfin Hẹrọdu.

Categories
ÌṢE ÀWỌN APOSTELI

ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 24

Ẹ̀sùn Tí Wọ́n fi Kan Paulu

1 Lẹ́yìn ọjọ́ marun-un, Anania olórí Alufaa dé pẹlu àwọn àgbààgbà ati agbẹjọ́rò kan tí ń jẹ́ Tatulu. Wọ́n ro ẹjọ́ Paulu fún gomina.

2 Nígbà tí wọ́n pe Paulu, Tatulu bẹ̀rẹ̀ sí rojọ́. Ó ní:

“Fẹliksi ọlọ́lá jùlọ, à ń jọlá alaafia tí ẹ mú wá lọpọlọpọ, a sì ń gbádùn oríṣìíríṣìí àtúnṣe tí ẹ̀ ń ṣe lọ́tùn-ún lósì fún àwọn ọmọ ilẹ̀ wa.

3 Ọjọ́ iwájú ni ẹ̀ ń rò tí ẹ fi ń ṣe èyí nígbà gbogbo. A dúpẹ́ pupọ lọ́wọ́ yín.

4 N kò fẹ́ gbà yín ní àkókò títí, mo bẹ̀ yín kí ẹ fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ gbọ́ ohun tí a níláti sọ ní ṣókí.

5 Onijamba eniyan ni ọkunrin yìí; rúkèrúdò ni ó ń dá sílẹ̀ láàrin àwọn Juu ní gbogbo àgbáyé. Ọ̀gá ni ninu ẹgbẹ́ àwọn Nasarene.

6 A ká a mọ́ ibi tí ó ti fẹ́ mú ohun ẹ̀gbin wọ inú Tẹmpili, a bá mú un. [A fẹ́ jẹ ẹ́ níyà gẹ́gẹ́ bí òfin wa.

7 Ṣugbọn ọ̀gágun Lisia wá fi ipá gbà á kúrò lọ́wọ́ wa, ni ó bá mú un lọ.

8 Òun ni ó pàṣẹ pé kí àwọn tí wọ́n fi ẹ̀sùn kàn án wá siwaju yín.] Bí ẹ bá wádìí lẹ́nu òun fúnrarẹ̀, ẹ óo rí i pé òtítọ́ ni gbogbo ẹjọ́ rẹ̀ tí a fi sùn yín.”

9 Àwọn Juu náà gbè é lẹ́sẹ̀; wọ́n ní bẹ́ẹ̀ ni gbogbo ọ̀rọ̀ tí ó sọ rí.

Paulu Sọ tẹnu Rẹ̀ níwájú Fẹliksi

10 Gomina wá mi orí sí Paulu. Paulu wá bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ tirẹ̀. Ó ní:

“Ó dùn mọ́ mi pé níwájú yín ni n óo ti sọ ti ẹnu mi. Nítorí mo mọ̀ pé ẹ ti ń ṣe onídàájọ́ ní orílẹ̀-èdè wa yìí fún ọpọlọpọ ọdún.

11 Kò ju ọjọ́ mejila lọ nisinsinyii tí mo lọ ṣọdún ní Jerusalẹmu. Ẹ lè wádìí èyí.

12 Ẹnìkan kò rí mi kí n máa bá ẹnikẹ́ni jiyàn ninu Tẹmpili. Bẹ́ẹ̀ ni ẹnìkan kò rí mi pé mo kó àwọn eniyan jọ láti dá rúkèrúdò sílẹ̀, ìbáà ṣe ninu ilé ìpàdé ni tabi níbikíbi láàrin ìlú.

13 Wọn kò lè rí ohunkohun wí tí ẹ lè rí dìmú ninu ẹjọ́ tí wọn wá ń rò mọ́ mi lẹ́sẹ̀ nisinsinyii.

14 Ṣugbọn mo jẹ́wọ́ ohun kan fun yín: lóòótọ́ ni mò ń sin Ọlọrun àwọn baba wa ní ọ̀nà tí ó yàtọ̀. Mo gba gbogbo ohun tí ó wà ninu ìwé Òfin ati ninu ìwé àwọn wolii.

15 Mo sì ń wojú Ọlọrun nítorí pé mo ní ìrètí kan náà tí àwọn ará ibí yìí pàápàá tí wọn ń rojọ́ mi ní, pé gbogbo òkú ni yóo jinde, ati ẹni rere ati ẹni burúkú.

16 Ìdí nìyí tí mo fi ń sa ipá mi kí ọkàn mi lè jẹ́ mi lẹ́rìí pé inú mi mọ́ sí Ọlọrun ati eniyan nígbà gbogbo.

17 “Ó ti tó ọdún mélòó kan tí mo ti dé Jerusalẹmu gbẹ̀yìn. Ìtọrẹ àánú ni mo mú wá fún àwọn orílẹ̀-èdè mi, kí n sì rúbọ.

18 Níbi tí mo gbé ń ṣe èyí, wọ́n rí mi ninu Tẹmpili. Mo ti wẹ ara mi mọ́ nígbà náà. N kò kó èrò lẹ́yìn, bẹ́ẹ̀ ni n kò fa ìjàngbọ̀n.

19 Ṣugbọn àwọn Juu kan láti Esia wà níbẹ̀. Àwọn ni ó yẹ kí wọ́n wá siwaju yín bí wọn bá ní ẹ̀sùn kan sí mi.

20 Tabi, kí àwọn tí wọ́n wà níhìn-ín fúnra wọn sọ nǹkan burúkú kan tí wọ́n rí pé mo ṣe nígbà tí mo wà níwájú ìgbìmọ̀.

21 Àfi gbolohun kan tí mo sọ nígbà tí mo dúró láàrin wọn, pé, ‘Ìdí tí a fi mú mi wá fún ìdájọ́ níwájú yín lónìí ni pé mo ní igbagbọ pé àwọn òkú yóo jinde.’ ”

22 Fẹliksi bá sún ọjọ́ ìdájọ́ siwaju. Ó mọ ohun tí ọ̀nà igbagbọ jẹ́ dáradára. Ó ní, “Nígbà tí ọ̀gágun Lisia bá dé, n óo sọ bí ọ̀rọ̀ yín ti rí lójú mi.”

23 Ó bá pàṣẹ fún balogun ọ̀rún pé kí ó máa ṣọ́ Paulu. Ó ní kí ó máa há a mọ́lé, ṣugbọn kí ó ní òmìnira díẹ̀, kí ó má sì dí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ láti ṣe ìtọ́jú rẹ̀.

Wọ́n Ti Paulu mọ́lé

24 Lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀ tí Fẹliksi ti dé pẹlu Durusila iyawo rẹ̀ tí ó jẹ́ Juu, ó ranṣẹ sí Paulu láti gbọ́ ọ̀rọ̀ nípa igbagbọ ninu Kristi Jesu lẹ́nu rẹ̀.

25 Nígbà tí Paulu bẹ̀rẹ̀ sí sọ tirẹ̀ nípa ìwà rere, ìkóra-ẹni-níjàánu, ati ìdájọ́ tí ń bọ̀, ẹ̀rù ba Fẹliksi. Ó bá sọ fún Paulu pé, “Ó tó gẹ́ẹ́ lónìí. Máa lọ. Nígbà tí mo bá ráyè n óo tún ranṣẹ pè ọ́.”

26 Sibẹ ó ń retí pé Paulu yóo fún òun ní owó. Nítorí náà, a máa ranṣẹ pè é lemọ́lemọ́ láti bá a sọ̀rọ̀.

27 Lẹ́yìn ọdún meji Pọkiu Fẹstu gba ipò Fẹliksi. Nítorí Fẹliksi ń wá ojurere àwọn Juu, ó fi Paulu sílẹ̀ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n.

Categories
ÌṢE ÀWỌN APOSTELI

ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 25

Paulu Gbé Ẹjọ́ Rẹ̀ Lọ siwaju Ọba Kesari

1 Lẹ́yìn ọjọ́ mẹta tí Fẹstu dé sí agbègbè ibi iṣẹ́ rẹ̀, ó lọ sí Jerusalẹmu láti Kesaria.

2 Àwọn olórí alufaa ati àwọn aṣiwaju àwọn Juu bá gbé ọ̀rọ̀ Paulu siwaju rẹ̀. Wọ́n ń bẹ̀ ẹ́ pé

3 kí ó ṣe oore kan fún wọn, kí ó fi Paulu ranṣẹ sí Jerusalẹmu. Èrò wọn ni láti dènà dè é, kí wọ́n baà lè pa á.

4 Ṣugbọn Fẹstu dá wọn lóhùn pé, “Àwọn ọmọ-ogun ń ṣọ́ Paulu ní Kesaria; èmi náà kò sì ní pẹ́ pada sibẹ.

5 Ẹ jẹ́ kí àwọn aṣiwaju yín bá mi kálọ kí wọ́n wá sọ bí wọ́n bá ní ẹ̀sùn kan sí i.”

6 Kò lò ju bí ọjọ́ mẹjọ tabi mẹ́wàá lọ pẹlu wọn, ni ó bá pada lọ sí Kesaria. Ní ọjọ́ keji ó jókòó ninu kóòtù, ó pàṣẹ pé kí wọ́n mú Paulu wá.

7 Nígbà tí Paulu dé, àwọn Juu tí wọ́n wá láti Jerusalẹmu tò yí i ká, wọ́n ń ro ẹjọ́ ńláńlá mọ́ ọn lẹ́sẹ̀ lọ́tùn-ún lósì, bẹ́ẹ̀ ni kò sí èyí tí ó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ ninu gbogbo ẹjọ́ tí wọ́n rò.

8 Nígbà tí Paulu bẹ̀rẹ̀ sí sọ ti ẹnu rẹ̀, ó ní, “N kò ṣe ohunkohun tí ó lòdì sí òfin àwọn Juu tabi sí Tẹmpili; n kò sì ṣẹ Kesari.”

9 Nítorí pé Fẹstu ń wá ojurere àwọn Juu, ó bi Paulu pé, “Ṣé o óo kálọ sí Jerusalẹmu, kí n dá ẹjọ́ yìí níbẹ̀?”

10 Paulu dáhùn ó ní, “Níwájú ìtẹ́ ìdájọ́ ọba Kesari ni mo gbé dúró, níbẹ̀ ni a níláti dá ẹjọ́ mi. N kò ṣẹ àwọn Juu, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin náà ti mọ̀ dájúdájú.

11 Bí mo bá rú òfin, tabi bí mo bá ṣe ohun tí ó yẹ kí á dá mi lẹ́bi ikú, n kò bẹ̀bẹ̀ pé kí ẹ má pa mí. Ṣugbọn bí kò bá sí ohun kan tí a lè rí dìmú ninu ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn mí, ẹnikẹ́ni kò lè fi mí wá ojurere wọn. Ẹ gbé ẹjọ́ mi lọ siwaju Kesari ọba.”

12 Fẹstu forí-korí pẹlu àwọn olùbádámọ̀ràn rẹ̀, ó wá dáhùn pé, “O ti gbé ẹjọ́ rẹ lọ siwaju ọba Kesari; nítorí náà o gbọdọ̀ lọ sọ́dọ̀ ọba Kesari.”

A Mú Paulu lọ siwaju Agiripa ati Berenike

13 Lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀, Agiripa ọba ati Berenike wá kí Fẹstu ní Kesaria.

14 Wọ́n pẹ́ díẹ̀ níbẹ̀. Fẹstu wá fi ọ̀rọ̀ Paulu siwaju ọba. Ó ní, “Ọkunrin kan wà níhìn-ín tí Fẹliksi fi sílẹ̀ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n.

15 Nígbà tí mo lọ sí Jerusalẹmu, àwọn olórí alufaa ati àwọn àgbààgbà àwọn Juu rojọ́ rẹ̀, wọ́n sì bẹ̀ mí pé kí n dá a lẹ́bi.

16 Mo dá wọn lóhùn pé kì í ṣe àṣà àwọn ará Romu láti fa ẹnikẹ́ni lé àwọn olùfisùn rẹ̀ lọ́wọ́ láì fún un ní anfaani láti fojúkojú pẹlu wọn, kí ó sì sọ ti ẹnu rẹ̀ nípa ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án.

17 Nígbà tí wọ́n bá mi wá síhìn-ín, n kò fi ọ̀rọ̀ náà falẹ̀. Ní ọjọ́ keji mo jókòó ní kóòtù, mo pàṣẹ kí wọ́n mú ọkunrin náà wá.

18 Nígbà tí àwọn tí ó fi ẹ̀sùn kàn án dìde láti sọ̀rọ̀, wọn kò mẹ́nuba irú àwọn ọ̀ràn tí mo rò pé wọn yóo sọ.

19 Àríyànjiyàn nípa ẹ̀sìn oriṣa wọn, ati nípa ẹnìkan tí ń jẹ́ Jesu ni ohun tí wọn ń jà sí. Jesu yìí ti kú, ṣugbọn Paulu ní ó wà láàyè.

20 Ọ̀rọ̀ náà rú mi lójú; mo bá bi ọkunrin náà bí ó bá fẹ́ lọ sí Jerusalẹmu, kí á ṣe ìdájọ́ ọ̀rọ̀ náà níbẹ̀.

21 Ṣugbọn Paulu ní kí á fi òun sílẹ̀ ní ìtìmọ́lé títí Kesari yóo fi lè gbọ́ ẹjọ́ òun. Mo bá pàṣẹ kí wọ́n fi í sílẹ̀ ní ìtìmọ́lé títí tí n óo fi lè fi ranṣẹ sí Kesari.”

22 Agiripa bá wí fún Fẹstu pé, “Èmi fúnra mi fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ lẹ́nu ọkunrin náà.”

Fẹstu dáhùn ó ní, “Ẹ óo gbọ́ ọ̀rọ̀ lẹ́nu rẹ̀ lọ́la.”

23 Nígbà tí ó di ọjọ́ keji, Agiripa ati Berenike bá dé pẹlu ayẹyẹ. Wọ́n wọ gbọ̀ngàn ní ààfin pẹlu àwọn ọ̀gágun ati àwọn eniyan jàǹkànjàǹkàn ní ìlú. Fẹstu bá pàṣẹ kí wọ́n mú Paulu wá.

24 Fẹstu wá sọ pé, “Agiripa aláyélúwà ati gbogbo ẹ̀yin eniyan tí ẹ bá wa péjọ níbí. Ọkunrin tí ẹ̀ ń wò yìí ni gbogbo àwọn Juu ní Jerusalẹmu ati níbí ń yan eniyan wá rí mi nípa rẹ̀, tí wọn ń kígbe pé kò yẹ kí ó tún wà láàyè mọ́.

25 Ní tèmi n kò rí ohun kan tí ó ṣe tí ó fi jẹ̀bi ikú. Ṣugbọn nígbà tí òun fúnrarẹ̀ ní kí á gbé ẹjọ́ òun lọ sí ọ̀dọ̀ Kesari, mo pinnu láti fi í ranṣẹ.

26 Ṣugbọn n kò ní ohun kan pàtó láti kọ sí oluwa mi nípa rẹ̀. Ìdí nìyí tí mo fi mú un wá siwaju yín, pàápàá siwaju Agiripa aláyélúwà, kí n lè rí ohun tí n óo kọ nípa rẹ̀ lẹ́yìn tí a bá ti yẹ ọ̀rọ̀ náà wò.

27 Mo rò pé kò bójú mu kí á fi ẹlẹ́wọ̀n ranṣẹ láìsọ ẹ̀sùn tí a fi kàn án.”

Categories
ÌṢE ÀWỌN APOSTELI

ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 26

Paulu Sọ Ti Ẹnu Rẹ̀ níwájú Agiripa

1 Agiripa wá yíjú sí Paulu, ó ní, “Ọ̀rọ̀ kàn ọ́. Sọ tìrẹ.” Paulu bá nawọ́, ó bẹ̀rẹ̀ sí ro ẹjọ́ tirẹ̀. Ó ní:

2 “Agiripa Ọba Aláyélúwà, mo ka ara mi sí olóríire pé níwájú yín ni n óo ti dáhùn sí gbogbo ẹjọ́ tí àwọn Juu pè mí lónìí,

3 pàápàá nítorí ẹ mọ gbogbo àṣà àwọn Juu dáradára, ẹ sì mọ àríyànjiyàn tí ó wà láàrin wọn. Nítorí náà mo bẹ̀ yín kí ẹ fi sùúrù gbọ́ ọ̀rọ̀ mi.

4 “Gbogbo àwọn Juu ni wọ́n mọ̀ bí mo ti lo ìgbésí ayé mi láti ìbẹ̀rẹ̀ ní ìgbà èwe mi nígbà tí mò ń gbé Jerusalẹmu láàrin àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè wa.

5 Ó ti pẹ́ tí wọ́n ti mọ̀ mí. Bí wọn bá fẹ́, wọ́n lè jẹ́rìí sí i pé ọ̀nà àwọn Farisi ni mo tẹ̀lé ninu ẹ̀sìn ìbílẹ̀ wa, ọ̀nà yìí ló sì le jù.

6 Wàyí ò! Ohun tí ó mú mi dúró nílé ẹjọ́ nisinsinyii ni pé mo ní ìrètí pé ìlérí tí Ọlọrun ṣe fún àwọn baba wa yóo ṣẹ.

7 Ìrètí yìí ni àwọn ẹ̀yà mejila tí ó wà ní orílẹ̀-èdè wa ní, tí wọ́n ṣe ń fi ìtara sin Ọlọrun tọ̀sán-tòru. Nítorí ohun tí à ń retí yìí ni àwọn Juu fi ń rojọ́ mi, Kabiyesi!

8 Kí ló ṣe wá di ohun tí ẹnikẹ́ni ninu yín kò lè gbàgbọ́ pé Ọlọrun a máa jí òkú dìde?”

9 “Nígbà kan rí èmi náà rò pé ó jẹ mí lógún láti tako orúkọ Jesu ará Nasarẹti. Kí ni n ò ṣe tán?

10 Mo ṣe díẹ̀ ní Jerusalẹmu. Pupọ ninu àwọn onigbagbọ ni mo tì mọ́lé, lẹ́yìn tí mo ti gba àṣẹ lọ́wọ́ àwọn olórí alufaa. Wọn á máa pa wọ́n báyìí, èmi náà á sì ní bẹ́ẹ̀ gan-an ló yẹ wọ́n.

11 Mò ń lọ láti ilé ìpàdé kan dé ekeji, mo sì ń jẹ wọ́n níyà, bóyá wọn a jẹ́ fẹnu wọn gbẹ̀ṣẹ̀. Ẹ̀tanú náà pọ̀ sí wọn tó bẹ́ẹ̀ tí mo fi lé wọn dé ìlú òkèèrè pàápàá.

Paulu Sọ Bí Ó Ti Ṣe Di Onigbagbọ

12 “Irú eré báyìí ni mò ń sá tí mò fi ń lọ sí Damasku ní ọjọ́ kan, pẹlu ìwé àṣẹ láti ọ̀dọ̀ àwọn olórí alufaa.

13 Kabiyesi, bí mo ti ń lọ lọ́nà lọ́sàn-án gangan, mo rí ìmọ́lẹ̀ láti ọ̀run tí ó mọ́lẹ̀ ju ti oòrùn lọ, tí ó tàn yí èmi ati àwọn tí ń bá mi lọ ká.

14 Bí gbogbo wa ti ṣubú lulẹ̀, mo gbọ́ ohùn kan tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀ ní èdè Heberu. Ó ní, ‘Saulu! Saulu! Kí ló dé tí o fi ń ṣe inúnibíni sí mi? O óo fara pa bí o bá ta igi ẹlẹ́gùn-ún nípàá.’

15 Mo wá bèèrè pé, ‘Ìwọ ta ni, Oluwa?’ Oluwa bá dáhùn ó ní, ‘Èmi ni Jesu tí ò ń ṣe inúnibíni sí.

16 Dìde nàró. Ohun tí mo fi farahàn ọ́ nìyí: mo ti yàn ọ́ láti jẹ́ iranṣẹ mi, kí o lè jẹ́rìí ohun tí o rí, ati ohun tí n óo fihàn ọ́.

17 N óo gbà ọ́ lọ́wọ́ àwọn eniyan Israẹli ati àwọn orílẹ̀-èdè yòókù tí n óo rán ọ sí.

18 Kí á lè là wọ́n lójú, kí á sì lè yí wọn pada láti inú òkùnkùn sinu ìmọ́lẹ̀, kí á lè gbà wọ́n lọ́wọ́ àṣẹ Satani, kí á sì fi wọ́n lé ọwọ́ Ọlọrun; kí wọ́n lè ní ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ nípa gbígbà mí gbọ́; kí wọ́n sì lè ní ogún pẹlu àwọn tí a ti yà sọ́tọ̀ fún Ọlọrun.’

Ẹ̀rí tí Paulu Jẹ́ fún Àwọn Juu ati fún Àwọn Orílẹ̀-Èdè Yòókù

19 “Nítorí náà, Agiripa Ọba Aláyélúwà, n kò ṣe àìgbọràn sí ìran tí ó ti ọ̀run wá.

20 Ṣugbọn mo kọ́kọ́ waasu fún àwọn tó wà ní Damasku, lẹ́yìn náà mo waasu fún àwọn tó wà ní Jerusalẹmu, ati ní gbogbo ilẹ̀ Judia, ati fún àwọn tí kì í ṣe Juu. Mò ń kéde pé kí wọ́n ronupiwada, kí wọ́n yipada sí Ọlọrun, kí wọn máa ṣe ohun tí ó yẹ ẹni tí ó ti ronupiwada.

21 Ìdí nìyí tí àwọn Juu fi mú mi ninu Tẹmpili, tí wọn ń fẹ́ pa mí.

22 Ṣugbọn Ọlọrun ràn mí lọ́wọ́. Títí di ọjọ́ òní mo ti dúró láti jẹ́rìí fún àwọn mẹ̀kúnnù ati àwọn eniyan pataki. N kò sọ ohunkohun yàtọ̀ sí ohun tí àwọn wolii ati Mose sọ pé yóo ṣẹlẹ̀.

23 Èyí ni pé Mesaya níláti jìyà; àtipé òun ni yóo kọ́ jí dìde kúrò ninu òkú tí yóo sì kéde iṣẹ́ ìmọ́lẹ̀ fún àwọn eniyan Ọlọrun ati fún àwọn tí kì í ṣe Juu.”

Paulu Fi Ẹ̀sìn Igbagbọ Lọ Agiripa

24 Bí Paulu ti ń sọ̀rọ̀ báyìí, Fẹstu ké mọ́ ọn pé, “Paulu, orí rẹ dàrú! Ìwé àmọ̀jù ti dà ọ́ lórí rú.”

25 Paulu dáhùn ó ní, “Fẹstu ọlọ́lá, orí mi kò dàrú. Òtítọ́ ọ̀rọ̀ gan-an ni mò ń sọ.

26 Gbogbo nǹkan wọnyi yé Kabiyesi, nítorí náà ni mo ṣe ń sọ ọ́ láìfòyà. Ó dá mi lójú pé kò sí ohun tí ó pamọ́ fún un ninu gbogbo ọ̀rọ̀ yìí. Nítorí kì í ṣe ní kọ̀rọ̀ ni nǹkan wọnyi ti ṣẹlẹ̀.

27 Agiripa Ọba Aláyélúwà, ṣé ẹ gba àwọn wolii gbọ́? Mo mọ̀ pé ẹ gbà wọ́n gbọ́.”

28 Agiripa bá bi Paulu pé, “Kíákíá báyìí ni o rò pé o lè sọ mí di Kristẹni?”

29 Paulu dáhùn, ó ní, “Ẹ̀bẹ̀ tí mò ń bẹ Ọlọrun ni pé, ó pẹ́ ni, ó yá ni, kí ẹ rí bí mo ti rí lónìí, láìṣe ti ẹ̀wọ̀n yìí. Kì í ṣe ẹ̀yin nìkan, ṣugbọn gbogbo àwọn tí ó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ mi lónìí.”

30 Agiripa bá dìde pẹlu gomina ati Berenike ati gbogbo àwọn tí ó jókòó pẹlu wọn.

31 Wọ́n bọ́ sápá kan, wọ́n ń sọ fún wọn pé, “Ọkunrin yìí kò ṣe ohunkohun tí ó fi jẹ̀bi ikú tabi ẹ̀wọ̀n.”

32 Agiripa wá sọ fún Fẹstu pé, “À bá dá ọkunrin yìí sílẹ̀ bí kò bá jẹ́ pé ó ti ní kí á gbé ẹjọ́ òun lọ siwaju Kesari.”

Categories
ÌṢE ÀWỌN APOSTELI

ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 27

Paulu Wọkọ̀ Lọ sí Romu

1 Nígbà tí wọ́n pinnu láti fi wá ranṣẹ sí Itali, wọ́n fi Paulu ati àwọn ẹlẹ́wọ̀n mìíràn lé balogun ọ̀rún kan tí ó ń jẹ́ Juliọsi lọ́wọ́, ó jẹ́ ọ̀gágun ti ẹgbẹ́ kan tí wọn ń pè ní Ọmọ-ogun Augustu.

2 A bá wọ ọkọ̀ ojú omi kan tí ó ń ti Adiramitu bọ̀ tí ó fẹ́ lọ sí ibi mélòó kan ní Esia. Ọkọ̀ bá ṣí; Arisitakọsi ará Tẹsalonika, ní ilẹ̀ Masedonia, ń bá wa lọ.

3 Ní ọjọ́ keji a gúnlẹ̀ ní Sidoni. Juliọsi ṣe dáradára sí Paulu. Ó jẹ́ kí ó lọ sọ́dọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, kí wọ́n fún un ní àwọn nǹkan tí ó nílò.

4 Láti ibẹ̀, a ṣíkọ̀, nítorí pé afẹ́fẹ́ ṣọwọ́ òdì sí wa, a gba apá Kipru níbi tí afẹ́fẹ́ kò ti fẹ́ pupọ.

5 A la agbami lọ sí apá èbúté Silisia ati Pamfilia títí a fi dé ìlú Mira ní ilẹ̀ Lisia.

6 Níbẹ̀ ni balogun ọ̀rún tí ó ń mú wa lọ ti rí ọkọ̀ Alẹkisandria kan tí ó ń lọ sí Itali. Ni a bá wọ̀ ọ́.

7 Fún ọpọlọpọ ọjọ́, ọkọ̀ kò lè yára rìn. Tipátipá ni a fi dé Kinidusi. Afẹ́fẹ́ ṣe ọwọ́ òdì sí wa. Ni a bá gba ẹ̀gbẹ́ Kirete níbi tí afẹ́fẹ́ kò ti fẹ́ pupọ. A kọjá ibi tí ilẹ̀ gbọọrọ ti wọ ààrin òkun tí wọn ń pè ní Salimone.

8 Tipátipá ni a fi ń lọ lẹ́bàá èbúté títí a fi dé ibìkan tí wọn ń pè ní Èbúté-rere tí kò jìnnà sí ìlú Lasia.

9 A pẹ́ níbẹ̀. Ewu ni bí a bá fẹ́ máa bá ìrìn àjò wa lọ nítorí ọjọ́ ààwẹ̀ ti kọjá. Paulu bá gbà wọ́n níyànjú;

10 ó ní, “Ẹ̀yin ará, mo wòye pé ewu wà ninu ìrìn àjò yìí. Ọpọlọpọ nǹkan ni yóo ṣòfò: ẹrù inú ọkọ̀, ati ọkọ̀ fúnrarẹ̀. Ewu wà fún gbogbo àwa tí a wà ninu ọkọ̀ pàápàá.”

11 Ṣugbọn ọ̀rọ̀ atukọ̀ ati ẹni tó ni ọkọ̀ wọ ọ̀gágun létí ju ohun tí Paulu sọ lọ.

12 Ibi tí wọ́n wà kì í ṣe ibi tí ó dára láti gbé ní ìgbà òtútù. Nítorí náà pupọ ninu àwọn tí wọ́n wà ninu ọkọ̀ rò pé kí àwọn kúrò níbẹ̀, bóyá wọn yóo lè dé Fonike níbi tí wọn yóo lè dúró ní ìgbà òtútù. Èbúté kan ní Kirete ni Fonike; ó kọjú sí ẹ̀gbẹ́ ìwọ̀ oòrùn gúsù ati ìwọ̀ oòrùn àríwá Kirete.

Ìjì Jà ní Òkun

13 Nígbà tí afẹ́fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí fẹ́ jẹ́jẹ́ láti apá gúsù, wọ́n rò pé ó ti bọ́ sí i fún wọn láti ṣe ohun tí wọ́n fẹ́ ṣe. Wọ́n bá ṣíkọ̀, wọ́n ń pẹ́ ẹ̀bá Kirete lọ.

14 Kò pẹ́ pupọ ni afẹ́fẹ́ líle kan láti erékùṣù náà bá bì lu ọkọ̀. Wọ́n ń pe afẹ́fẹ́ náà ní èyí tí ó wá láti àríwá ìlà oòrùn.

15 Afẹ́fẹ́ líle yìí bá bẹ̀rẹ̀ sí taari ọkọ̀. Nítorí pé kò sí ọ̀nà láti fi yí ọkọ̀, kí ó kọjú sí atẹ́gùn yìí, a fi í sílẹ̀ kí afẹ́fẹ́ máa gbé e lọ.

16 A sinmi díẹ̀ nígbà tí a gba gúsù erékùṣù kékeré kan tí ó ń jẹ́ Kauda kọjá. Níbẹ̀, a fi tipátipá so ọkọ̀ kékeré tí ó wà lára ọkọ̀ ńlá wa, kí ó má baà fọ́.

17 Wọ́n bá fà á sinu ọkọ̀ ńlá, wọ́n wá fi okùn so ó mọ́ ara ọkọ̀ ńlá. Ẹ̀rù ń bà wọ́n kí wọn má forí ọkọ̀ sọ ilẹ̀ iyanrìn ní Sitisi, wọ́n bá ta aṣọ-ọkọ̀, kí atẹ́gùn lè máa gbé ọkọ̀ náà lọ.

18 Ní ọjọ́ keji, nígbà tí ìjì túbọ̀ le pupọ, a bá da ẹrù inú ọkọ̀ sinu òkun.

19 Ní ọjọ́ kẹta, ọwọ́ ara wọn ni wọ́n fi da àwọn ohun èèlò inú ọkọ̀ náà sinu òkun.

20 Fún ọpọlọpọ ọjọ́ ni oòrùn kò ràn tí ìràwọ̀ kò sì yọ. Ìjì ńlá ń jà. A bá sọ ìrètí nù pé a tún lè là mọ́.

21 Lẹ́yìn tí wọ́n ti wà fún ọpọlọpọ ọjọ́, láì jẹun, Paulu dìde dúró láàrin wọn, ó ní, “Ẹ̀yin eniyan, ẹ̀ bá ti gbọ́ tèmi kí ẹ má ṣíkọ̀ ní Kirete. Irú ewu ati òfò yìí ìbá tí sí.

22 Ṣugbọn bí ó ti rí yìí náà, mo gbà yín níyànjú pé kí ẹ ṣara gírí. Ẹ̀mí ẹnikẹ́ni ninu yín kò ní ṣòfò; ọkọ̀ nìkan ni yóo ṣòfò.

23 Nítorí ní alẹ́ àná, angẹli Ọlọrun mi, tí mò ń sìn dúró tì mí, ó ní,

24 ‘Má bẹ̀rù, Paulu. Dandan ni kí o dé iwájú Kesari. Mo fẹ́ kí o mọ̀ pé Ọlọrun ti fi ẹ̀mí gbogbo àwọn ẹni tí ó wọkọ̀ pẹlu rẹ jíǹkí rẹ.’

25 Nítorí náà ẹ̀yin eniyan, ẹ ṣara gírí, nítorí mo gba Ọlọrun gbọ́ pé bí ó ti sọ fún mi ni yóo rí.

26 Ṣugbọn ọkọ̀ wa yóo fàyà sọlẹ̀ ní erékùṣù kan.”

27 Nígbà tí ó di alẹ́ kẹrinla tí afẹ́fẹ́ ti ń ti ọkọ̀ wa kiri ninu òkun Adiria, àwọn atukọ̀ fura ní òru pé a kò jìnnà sí ilẹ̀.

28 Wọ́n sọ ìwọ̀n sinu òkun, wọ́n rí i pé ó jìn tó ogoji mita. Nígbà tí a sún díẹ̀, wọ́n tún sọ ìwọ̀n sinu òkun, wọ́n rí i pé ó jìn tó ọgbọ̀n mita.

29 Wọ́n wá ń bẹ̀rù pé kí ọkọ̀ má forí sọ òkúta. Wọ́n bá ju irin ìdákọ̀ró mẹrin sinu omi ní ẹ̀yìn ọkọ̀; wọ́n bá ń gbadura pé kí ilẹ̀ tètè mọ́.

30 Àwọn atukọ̀ ń wá bí wọn yóo ti ṣe sálọ kúrò ninu ọkọ̀. Wọ́n bá sọ ọkọ̀ kékeré sórí òkun bí ẹni pé wọ́n fẹ́ sọ ìdákọ̀ró tí ó wà níwájú ọkọ̀ sinu òkun.

31 Paulu wá sọ fún balogun ọ̀rún ati àwọn ọmọ-ogun náà pé, “Bí àwọn ará ibí yìí kò bá dúró ninu ọkọ̀, kò sí bí ẹ ti ṣe lè là.”

32 Àwọn ọmọ-ogun bá gé okùn tí wọ́n fi so ọkọ̀ kékeré náà, wọ́n jẹ́ kí ìgbì gbé e lọ.

33 Nígbà tí ilẹ̀ fẹ́rẹ̀ mọ́, Paulu gbà wọ́n níyànjú pé kí gbogbo wọn jẹun. Ó ní, “Ó di ọjọ́ mẹrinla lónìí, tí ọkàn yín kò tíì balẹ̀ tí ẹ̀ ń gbààwẹ̀; tí ẹ kò jẹ ohunkohun.

34 Nítorí náà, mo bẹ̀ yín, ẹ jẹun; èyí ṣe pataki bí ẹ ò bá fẹ́ kú. Irun orí ẹnikẹ́ni kò tilẹ̀ ní ṣòfò.”

35 Nígbà tí ó ti sọ báyìí tán, òun náà mú burẹdi, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun níwájú gbogbo wọn, ó bù ú, ó bá bẹ̀rẹ̀ sí jẹ ẹ́.

36 Ni gbogbo wọn bá ṣara gírí, àwọn náà bá jẹun.

37 Gbogbo àwa tí a wà ninu ọkọ̀ náà jẹ́ igba ó lé mẹrindinlọgọrin (276).

38 Nígbà tí wọ́n jẹun yó tán, wọ́n da ọkà tí ó kù sinu òkun láti mú kí ọkọ̀ lè fúyẹ́ sí i.

Ọkọ̀ Rì

39 Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, wọ́n rí èbúté ṣugbọn wọn kò mọ ibẹ̀. Wọ́n wá ṣe akiyesi ibìkan tí òkun ti wọ ààrin ilẹ̀ tí ó ní iyanrìn. Wọ́n rò pé bóyá àwọn lè tukọ̀ dé èbúté ibẹ̀.

40 Wọ́n bá já àwọn ìdákọ̀ró, wọ́n jẹ́ kí wọ́n rì sinu omi. Ní àkókò yìí kan náà, wọ́n tú okùn lára àwọn ajẹ̀ tí wọ́n fi ń tukọ̀. Wọ́n wá ta aṣọ-ọkọ̀ tí ó wà lókè patapata níwájú ọkọ̀. Atẹ́gùn wá ń fẹ́ ọkọ̀ lọ sí èbúté.

41 Ṣugbọn ọkọ̀ rọ́lu ilẹ̀ níbi tí òkun kò jìn, ni ó bá dúró gbọnin. Iwájú ọkọ̀ wọ inú iyanrìn, kò ṣe é yí. Ẹ̀yìn ọkọ̀ kò kanlẹ̀, ìgbì wá bẹ̀rẹ̀ sí fọ́ ọ bí ó ti ń bì lù ú.

42 Àwọn ọmọ-ogun wá ń gbèrò pé kí àwọn pa àwọn ẹlẹ́wọ̀n, kí wọn má baà lúwẹ̀ẹ́ sálọ.

43 Ṣugbọn balogun ọ̀rún kò jẹ́ kí àwọn ọmọ-ogun ṣe ìfẹ́ inú wọn, nítorí pé ó fẹ́ mú Paulu gúnlẹ̀ ní alaafia. Ó pàṣẹ pé kí àwọn tí ó bá lè lúwẹ̀ẹ́ kọ́kọ́ bọ́ sómi, kí wọ́n lúwẹ̀ẹ́ lọ sí èbúté.

44 Kí àwọn yòókù wá tẹ̀lé wọn, kí wọ́n dì mọ́ pákó tabi kí wọ́n dì mọ́ ara ọkọ̀ tí ó ti fọ́. Báyìí ni gbogbo wa ṣe gúnlẹ̀ ní alaafia.

Categories
ÌṢE ÀWỌN APOSTELI

ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 28

Ohun tí Paulu Ṣe ní Erékùṣù Mẹlita

1 Nígbà tí a ti gúnlẹ̀ ní alaafia tán ni a tó mọ̀ pé Mẹlita ni wọ́n ń pe erékùṣù náà.

2 Àwọn ará ibẹ̀ ṣe ìtọ́jú wa lọpọlọpọ. Wọ́n fi ọ̀yàyà gba gbogbo wa. Wọ́n dáná fún wa nítorí pé òjò ti bẹ̀rẹ̀ sí rọ̀, òtútù sì mú.

3 Nígbà tí Paulu di ìdì igi kan, tí ó dà á sinu iná, bẹ́ẹ̀ ni paramọ́lẹ̀ kan yọ nígbà tí iná rà á, ló bá so mọ́ Paulu lọ́wọ́.

4 Nígbà tí àwọn ará Mẹlita rí ejò náà tí ó ń ṣe dìrọ̀dìrọ̀ ní ọwọ́ Paulu, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sọ láàrin ara wọn pé, “Dájúdájú apànìyàn ni ọkunrin yìí. Ó yọ ninu ewu òkun, ṣugbọn Ọlọrun ẹ̀san kò gbà pé kí ó yè.”

5 Paulu kàn gbọn ejò náà sinu iná ni, ohun burúkú kan kò sì ṣẹlẹ̀ sí i.

6 Àwọn eniyan ń retí pé ọwọ́ rẹ̀ yóo wú, tabi pé lójijì yóo ṣubú lulẹ̀, yóo sì kú. Nígbà tí wọ́n retí títí, tí wọn kò rí i kí nǹkankan ṣe é, wọ́n yí èrò wọn pada, wọ́n ní, “Irúnmọlẹ̀ ni!”

7 Ilẹ̀ tí ó wá yí wọn ká jẹ́ ti Pubiliusi, baálẹ̀ erékùṣù náà. Ó gbà wá sílé fún ọjọ́ mẹta, ó sì ṣe wá lálejò.

8 Ní àkókò yìí baba Pubiliusi ń ṣàìsàn: ibà ń ṣe é, ó sì ń ya ìgbẹ́-ọ̀rìn. Paulu bá wọ iyàrá tọ̀ ọ́ lọ. Lẹ́yìn tí ó gbadura, ó gbé ọwọ́ lé e, ó sì wò ó sàn.

9 Nígbà tí èyí ṣẹlẹ̀, àwọn yòókù tí ó ń ṣàìsàn ní erékùṣù náà bá ń wá sọ́dọ̀ Paulu, ó sì ń wò wọ́n sàn.

10 Wọ́n yẹ́ wa sí pupọ. Nígbà tí a óo sì fi ṣíkọ̀, wọ́n fún wa ní àwọn nǹkan tí a lè nílò lọ́nà.

Paulu Dé Romu

11 Lẹ́yìn oṣù mẹta tí a ti wà níbẹ̀, a wọ ọkọ̀ ojú omi Alẹkisandria kan tí ó ti dúró ní erékùṣù yìí fún ìgbà òtútù. Ó ní ère ìbejì níwájú rẹ̀.

12 Nígbà tí a dé Sirakusi, a dúró níbẹ̀ fún ọjọ́ mẹta.

13 Láti ibẹ̀ a ṣíkọ̀, a dé Regiumu. Ní ọjọ́ keji, afẹ́fẹ́ kan láti gúsù fẹ́ wá, ni a bá tún ṣíkọ̀. Ní ọjọ́ kẹta a dé Puteoli.

14 A rí àwọn onigbagbọ níbẹ̀. Wọ́n rọ̀ wá kí á dúró lọ́dọ̀ wọn, a bá ṣe ọ̀sẹ̀ kan níbẹ̀. Báyìí ni a ṣe dé Romu.

15 Àwọn onigbagbọ ibẹ̀ ti gbọ́ ìròyìn wa. Wọ́n bá wá pàdé wa lọ́nà, wọ́n dé Ọjà Apiusi ati Ilé-èrò Mẹta. Nígbà tí Paulu rí wọn, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun, èyí sì dá a lọ́kàn le.

Paulu Waasu ní Romu

16 Nígbà tí a wọ Romu, wọ́n gba Paulu láàyè láti wá ilé gbé pẹlu ọmọ-ogun kan tí wọ́n fi ṣọ́ ọ.

17 Lẹ́yìn ọjọ́ mẹta Paulu pe àwọn aṣiwaju àwọn Juu jọ. Nígbà tí ẹsẹ̀ wọn pé, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ̀yin alàgbà, n kò ṣe ohunkohun tí ó lòdì sí àwọn eniyan wa tabi sí àṣà àwọn baba ńlá wa tí wọ́n fi fi mí lé àwọn ará Romu lọ́wọ́ tí wọ́n sì fi mí sinu ẹ̀wọ̀n láti Jerusalẹmu.

18 Nígbà tí wọ́n wádìí ọ̀rọ̀ lẹ́nu mi, wọ́n fẹ́ dá mi sílẹ̀ nítorí wọn kò rí ohunkohun tí mo ṣe tí wọ́n fi lè dá mi lẹ́bi ikú.

19 Ṣugbọn nígbà tí àwọn Juu kò gbà pé kí wọ́n dá mi sílẹ̀, kò sí ohun tí mo tún lè ṣe jù pé kí n gbé ẹjọ́ mi wá siwaju Kesari lọ. Kì í ṣe pé mo ní ẹjọ́ kankan láti bá orílẹ̀-èdè wa rò.

20 Ìdí nìyí tí mo fi ranṣẹ pè yín láti ri yín kí n sì ba yín sọ̀rọ̀; nítorí ohun tí Israẹli ń retí ni wọ́n ṣe fi ẹ̀wọ̀n so mí báyìí.”

21 Wọ́n dá a lóhùn pé, “A kò rí ìwé gbà nípa rẹ láti Judia; bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni ninu àwọn ará wa kò débí láti ròyìn rẹ tabi láti sọ̀rọ̀ rẹ ní ibi.

22 A rò pé ó dára kí á gbọ́ ohun tí o ní lọ́kàn, nítorí pé ó ti dé etígbọ̀ọ́ wa pé níbi gbogbo ni àwọn eniyan lòdì sí ẹgbẹ́ tí ó yàtọ̀ yìí.”

23 Wọ́n bá dá ọjọ́ tí wọn yóo wá fún un. Nígbà tí ọjọ́ pé, pupọ ninu wọn wá kí i. Ó bá dá ọ̀rọ̀ sílẹ̀, ó ń fi tẹ̀dùntẹ̀dùn ṣe àlàyé ìjọba Ọlọrun fún wọn, ó sì ń fi ẹ̀rí tí ó wà ninu ìwé Òfin Mose ati ìwé wolii nípa Jesu hàn wọ́n láti òwúrọ̀ títí di ìrọ̀lẹ́.

24 Àwọn mìíràn gba ohun tí ó sọ gbọ́, ṣugbọn àwọn mìíràn kò gbàgbọ́.

25 Nígbà tí ohùn wọn kò dọ́gba láàrin ara wọn, wọ́n bá ń túká lọ. Paulu wá tún sọ gbolohun kan, ó ní, “Òtítọ́ ni Ẹ̀mí Mímọ́ sọ láti ẹnu wolii Aisaya sí àwọn baba-ńlá yín.

26 Ó ní,

‘Lọ sọ fún àwọn eniyan yìí pé:

Ẹ óo fetí yín gbọ́, ṣugbọn kò ní ye yín;

Ẹ óo wò ó títí, ṣugbọn ẹ kò ní mọ̀ ọ́n.

27 Nítorí ọkàn àwọn eniyan yìí kò ṣí;

wọ́n ti di alágbọ̀ọ́ya,

wọ́n ti dijú.

Bí kò bá ṣe bẹ́ẹ̀,

wọn ìbá fi ojú wọn ríran,

wọn ìbá fetí gbọ́ràn,

òye ìbá yé wọn,

wọn ìbá yipada;

èmi ìbá sì wò wọ́n sàn.’

28 “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé a ti rán iṣẹ́ ìgbàlà Ọlọrun yìí sí àwọn tí kì í ṣe Juu. Àwọn ní tiwọn yóo gbọ́.”

29 Nígbà tí Paulu ti sọ báyìí tán, àwọn Juu túká, wọ́n ń bá ara wọn jiyàn kíkankíkan.

30 Fún ọdún meji gbáko ni Paulu fi gbé ninu ilé tí ó gbà fúnra rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni ó ń gba gbogbo àwọn tí ó ń wá rí i.

31 Ó ń waasu ìjọba Ọlọrun. Ó ń kọ́ àwọn eniyan nípa Oluwa Jesu Kristi láì bẹ̀rù ohunkohun. Ẹnikẹ́ni kò sì dí i lọ́wọ́.