Categories
ÌṢE ÀWỌN APOSTELI

ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 10

Ìtàn Peteru ati Kọniliu

1 Ọkunrin kan wà ní Kesaria tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Kọniliu. Ó jẹ́ balogun ọ̀rún ti ẹgbẹ́ tí à ń pè ní Ẹgbẹ́ Ọmọ Ogun Itali.

2 Olùfọkànsìn ni. Òun ati gbogbo ìdílé rẹ̀ sì bẹ̀rù Ọlọrun. A máa ṣàánú àwọn eniyan lọpọlọpọ, a sì máa gbadura sí Ọlọrun nígbà gbogbo.

3 Ní ọjọ́ kan, ní nǹkan agogo mẹta ọ̀sán, ó rí ìran kan. Angẹli Ọlọrun wọlé tọ̀ ọ́ wá, ó ní, “Kọniliu!”

4 Kọniliu bá tẹjú mọ́ ọn. Ẹ̀rù bà á, ó ní, “Kí ló dé, alàgbà?”

Angẹli yìí bá sọ fún un pé, “Adura rẹ ti gbà; iṣẹ́ àánú rẹ ti gòkè lọ siwaju Ọlọrun. Ọlọrun sì ti ranti rẹ.

5 Nisinsinyii wá rán àwọn kan lọ sí Jọpa, kí wọn lọ pe ẹnìkan tí ń jẹ́ Simoni, tí àpèlé rẹ̀ ń jẹ́ Peteru, kí ó wá.

6 Ó dé sílé ẹnìkan tí ń jẹ́ Simoni, tí ń ṣe òwò awọ, tí ilé rẹ̀ wà létí òkun.”

7 Bí angẹli tí ó ń bá a sọ̀rọ̀ ti lọ tán, ó pe meji ninu àwọn iranṣẹ rẹ̀ ati ọmọ-ogun olùfọkànsìn kan, ọ̀kan ninu àwọn tí ó máa ń dúró tì í tímọ́tímọ́.

8 Ó ròyìn ohun gbogbo fún wọn, ó bá rán wọn lọ sí Jọpa.

9 Ní ọjọ́ keji, bí wọ́n ti ń bá ìrìn àjò wọn lọ, tí wọ́n súnmọ́ Jọpa, Peteru gun òkè ilé lọ láti gbadura ní nǹkan agogo mejila ọ̀sán.

10 Ebi dé sí i, ó wá ń wá nǹkan tí yóo jẹ. Bí wọ́n ti ń tọ́jú oúnjẹ lọ́wọ́, Peteru bá rí ìran kan.

11 Ó rí ọ̀run tí ó pínyà, tí nǹkankan bí aṣọ tí ó fẹ̀, tí ó ní igun mẹrin, ń bọ̀ wálẹ̀, títí ó fi dé ilẹ̀.

12 Gbogbo ẹranko ẹlẹ́sẹ̀ mẹrin ati oríṣìíríṣìí ẹranko tí ó ń fi àyà fà, ati ẹyẹ ojú ọ̀run ni ó wà ninu rẹ̀.

13 Ó wá gbọ́ ohùn ẹnìkan tí ó ń bá a sọ̀rọ̀, ó ní, “Peteru dìde, pa ẹran kí o jẹ ẹ́!”

14 Ṣugbọn Peteru dáhùn pé, “Èèwọ̀ Oluwa! N kò jẹ ẹrankẹ́ran tabi ẹran àìmọ́ kan rí.”

15 Ohùn náà tún dún létí rẹ̀ lẹẹkeji pé, “Ohun tí Ọlọrun bá ti sọ di mímọ́, o kò gbọdọ̀ pè é ní ohun àìmọ́!”

16 Èyí ṣẹlẹ̀ lẹẹmẹta. Lẹsẹkẹsẹ a tún gbé aṣọ náà lọ sókè ọ̀run.

17 Ìran tí Peteru rí yìí rú u lójú. Bí ó ti ń rò ó pé kí ni ìtumọ̀ ohun tí òun rí yìí, àwọn tí Kọniliu rán sí i ti wádìí ibi tí ilé Simoni wà, wọ́n ti dé ẹnu ọ̀nà.

18 Wọ́n ké “Àgò!” wọ́n sì ń bèèrè bí Simoni tí àpèlé rẹ̀ ń jẹ́ Peteru bá dé sibẹ.

19 Bí Peteru ti ń ronú lórí ìran yìí, Ẹ̀mí sọ fún un pé, “Àwọn ọkunrin mẹtań wá ọ.

20 Dìde, lọ sí ìsàlẹ̀, kí o bá wọn lọ láì kọminú nítorí èmi ni mo rán wọn.”

21 Nígbà tí Peteru dé ìsàlẹ̀, ó wí fún àwọn ọkunrin náà pé, “Èmi tí ẹ̀ ń wá nìyí, kí ni ẹ̀ ń fẹ́ o?”

22 Wọ́n bá dáhùn pé, “Kọniliu ọ̀gágun ni ó rán wa wá; eniyan rere ni, ó sì bẹ̀rù Ọlọrun tóbẹ́ẹ̀ tí gbogbo àwọn ọmọ Juu fi lè jẹ́rìí sí i. Angẹli Oluwa ni ó sọ fún un pé kí ó ranṣẹ pè ọ́ wá sí ilé rẹ̀, kí ó lè gbọ́ ọ̀rọ̀ lẹ́nu rẹ.”

23 Ni Peteru bá pè wọ́n wọlé, ó gbà wọ́n lálejò.

Nígbà tí ó di ọjọ́ keji, ó dìde, ó bá wọn lọ. Àwọn kan ninu àwọn ọmọ ìjọ ní Jọpa sì tẹ̀lé wọn.

24 Ní ọjọ́ keji tí wọ́n gbéra ní Jọpa ni wọ́n dé Kesaria. Kọniliu ti ń retí wọn. Ó ti pe àwọn ẹbí ati àwọn tí ó jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́ jọ.

25 Bí Peteru ti fẹ́ wọlé, Kọniliu lọ pàdé rẹ̀. Ó kúnlẹ̀, ó sì foríbalẹ̀.

26 Ṣugbọn Peteru fà á dìde, ó ní, “Dìde! Eniyan ni èmi náà.”

27 Bí ó ti ń bá a sọ̀rọ̀, bẹ́ẹ̀ ni ó bá a wọlé. Ó rí ọ̀pọ̀ eniyan tí ó ti péjọ.

28 Ó sọ fún wọn pé, “Ó ye yín pé ó lòdì sí òfin wa pé kí ẹni tíí ṣe Juu kí ó ní nǹkan í ṣe pẹlu ẹni tí ó jẹ́ ẹ̀yà mìíràn, tabi kí ó lọ bẹ̀ ẹ́ wò ninu ilé rẹ̀. Ṣugbọn Ọlọrun ti fihàn mí pé n kò gbọdọ̀ pe ẹnikẹ́ni ni eniyan lásán tabi aláìmọ́.

29 Ìdí tí mo ṣe wá láì kọminú nìyí nígbà tí o ranṣẹ sí mi. Mo wá fẹ́ mọ ìdí rẹ̀ tí o fi ranṣẹ sí mi.”

30 Kọniliu dáhùn pé, “Ní ijẹrin, ní déédé àkókò yìí, mo ń gbadura ninu ilé mi ní agogo mẹta ọ̀sán. Ọkunrin kan bá yọ sí mi, ó wọ aṣọ dídán.

31 Ó ní, ‘Kọniliu, Ọlọrun ti gbọ́ adura rẹ, ó sì ti ranti iṣẹ́ àánú rẹ.

32 Nítorí náà, ranṣẹ lọ sí Jọpa, kí o lọ pe Simoni tí àdàpè rẹ̀ ń jẹ́ Peteru wá. Ó dé sílé Simoni tí ń ṣe òwò awọ, létí òkun.’

33 Lẹsẹkẹsẹ ni mo bá ranṣẹ sí ọ. O ṣeun tí o wá. Nisinsinyii gbogbo wa wà níwájú Ọlọrun láti gbọ́ ohun gbogbo tí Oluwa ti pa láṣẹ fún ọ láti sọ.”

Ọ̀rọ̀ Tí Peteru Sọ nílé Kọniliu

34 Peteru bá tẹnu bọ̀rọ̀. Ó ní, “Ó wá yé mi gan-an pé Ọlọrun kì í ṣe ojuṣaaju.

35 Ẹnikẹ́ni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, tí ó sì ń ṣe rere ni yóo fà mọ́ra láì bèèrè orílẹ̀-èdè tí ó jẹ́.

36 Ẹ mọ iṣẹ́ tí ó rán sí àwọn ọmọ Israẹli, ọ̀rọ̀ ìyìn rere alaafia nípasẹ̀ Jesu Kristi, ẹni tíí ṣe Oluwa gbogbo eniyan.

37 Ẹ mọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ní gbogbo Judia. Ó bẹ̀rẹ̀ láti Galili lẹ́yìn ìrìbọmi tí Johanu ń sọ pé kí àwọn eniyan ṣe.

38 Ẹ mọ̀ nípa Jesu ará Nasarẹti, bí Ọlọrun ti ṣe yàn án, tí ó fún un ní Ẹ̀mí Mímọ́ ati agbára; bí ó ti ṣe ń lọ káàkiri tí ó ń ṣe rere, tí ó ń wo gbogbo àwọn tí Satani ti ń dá lóró sàn, nítorí Ọlọrun wà pẹlu rẹ̀.

39 Àwa yìí ni ẹlẹ́rìí gbogbo ohun tí ó ṣe ní ilẹ̀ àwọn Juu ati ní Jerusalẹmu. Wọ́n kan ọkunrin yìí mọ́ agbelebu.

40 Ṣugbọn Ọlọrun jí i dìde ní ọjọ́ kẹta, ó sì jẹ́ kí eniyan rí i.

41 Kì í ṣe gbogbo eniyan ni ó rí i bíkòṣe àwọn ẹlẹ́rìí tí Ọlọrun ti yàn tẹ́lẹ̀, àwa tí a bá a jẹ, tí a bá a mu lẹ́yìn tí ó jinde kúrò ninu òkú.

42 Ó wá pàṣẹ fún wa láti waasu fún àwọn eniyan, kí á fi yé wọn pé Jesu yìí ni ẹni tí Ọlọrun ti yàn láti jẹ́ onídàájọ́ àwọn tí ó ti kú ati àwọn tí ó wà láàyè.

43 Òun ni gbogbo àwọn wolii ń jẹ́rìí sí, tí wọ́n sọ pé gbogbo ẹni tí ó bá gbà á gbọ́ yóo ní ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ ní orúkọ rẹ̀.”

Àwọn Tí Kì Í ṣe Juu Gba Ẹ̀mí Mímọ́

44 Bí Peteru ti ń sọ̀rọ̀ báyìí lọ́wọ́, kò tíì dákẹ́ ọ̀rọ̀ tí ń sọ, bẹ́ẹ̀ ni Ẹ̀mí Mímọ́ bá bà lé gbogbo àwọn tí ó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ náà.

45 Ẹnu ya àwọn onigbagbọ tí wọ́n jẹ́ Juu tí wọ́n bá Peteru wá nítorí àwọn tí kì í ṣe Juu rí ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́ gbà lọ́fẹ̀ẹ́ ati lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́.

46 Wọ́n gbọ́ tí wọn ń fi oríṣìíríṣìí èdè sọ̀rọ̀, tí wọn ń yin Ọlọrun fún iṣẹ́ ńlá rẹ̀. Peteru bá bèèrè pé,

47 “Ta ló rí ohun ìdíwọ́ kan, ninu pé kí á ṣe ìrìbọmi fún àwọn wọnyi, tí wọ́n gba Ẹ̀mí Mímọ́ bí àwa náà ti gbà á?”

48 Lẹ́yìn náà, ó pàṣẹ pé kí wọ́n ṣe ìrìbọmi ní orúkọ Jesu Kristi. Wọ́n bá bẹ̀ ẹ́ kí ó dúró lọ́dọ̀ wọn fún ọjọ́ díẹ̀.

Categories
ÌṢE ÀWỌN APOSTELI

ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 11

Peteru Ròyìn fún Ìjọ ní Jerusalẹmu

1 Àwọn aposteli ati àwọn onigbagbọ yòókù tí ó wà ní Judia gbọ́ pé àwọn tí kì í ṣe Juu náà ti gba ọ̀rọ̀ Ọlọrun.

2 Nígbà tí Peteru pada dé Jerusalẹmu, àwọn onigbagbọ tí ó jẹ́ Juu dá àríyànjiyàn sílẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ náà.

3 Wọ́n ní, “O wọlé tọ àwọn eniyan tí kò kọlà lọ, o sì bá wọn jẹun!”

4 Peteru bá tẹnu bọ̀rọ̀, ó ro gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún wọn lẹ́sẹẹsẹ.

5 Ó ní, “Ìlú Jọpa ni mo wà tí mò ń gbadura, ni mo bá rí ìran kan. Nǹkankan tí ó dàbí aṣọ tí ó fẹ̀, tí wọ́n so ní igun mẹrin ń sọ̀kalẹ̀ bọ̀ láti ọ̀run títí ó fi dé ọ̀dọ̀ mi.

6 Mo tẹjú mọ́ ọn láti wo ohun tí ó wà ninu rẹ̀. Mo bá rí àwọn ẹranko ẹlẹ́sẹ̀ mẹrin ati àwọn ẹranko ìgbẹ́ ati àwọn ẹranko tí ń fi àyà wọ́, ati àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run.

7 Mo wá gbọ́ ohùn ẹnìkan tí ó sọ fún mi pé, ‘Peteru, dìde, pa àwọn ẹran tí o bá fẹ́, kí o sì jẹ.’

8 Ṣugbọn mo ní, ‘Èèwọ̀, Oluwa! N kò jẹ ẹrankẹ́ran tabi ẹran àìmọ́ kan rí.’

9 Lẹẹkeji ohùn náà tún wá láti ọ̀run. Ó ní, ‘Ohunkohun tí Ọlọrun bá ti sọ di mímọ́, ìwọ kò gbọdọ̀ pè é ní aláìmọ́ mọ́.’

10 Ẹẹmẹta ni ó ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀, ni nǹkankan bá tún fa gbogbo wọn pada sí ọ̀run.

11 Lákòókò náà gan-an ni àwọn ọkunrin mẹta tí a rán sí mi láti Kesaria dé ilé tí mo wà.

12 Ẹ̀mí wá sọ fún mi pé kí n bá wọn lọ láì kọminú. Mẹfa ninu àwọn arakunrin bá mi lọ. A bá wọ ilé ọkunrin náà.

13 Ó sọ fún wa bí òun ti ṣe rí angẹli tí ó dúró ninu ilé òun tí ó sọ pé, ‘Ranṣẹ lọ sí Jọpa, kí o pe Simoni tí àpèlé rẹ̀ ń jẹ́ Peteru wá.

14 Òun ni yóo sọ ọ̀rọ̀ fún ọ nípa bí ìwọ ati ìdílé rẹ yóo ṣe ní ìgbàlà.’

15 Bí mo ti bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ ni Ẹ̀mí Mímọ́ bá bà lé wọn bí ó ti bà lé wa ní àkọ́kọ́.

16 Ó mú mi ranti ọ̀rọ̀ Oluwa nígbà tí ó sọ pé, ‘Omi ni Johanu fi ṣe ìwẹ̀nùmọ́ fun yín, ṣugbọn Ẹ̀mí Mímọ́ ni a óo fi ṣe ìwẹ̀nùmọ́ yín.’

17 Nítorí náà bí Ọlọrun bá fún wọn ní ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ kan náà bí ó ti fún àwa tí a gba Oluwa Jesu Kristi gbọ́, tèmi ti jẹ́, tí n óo wá dí Ọlọrun lọ́nà?”

18 Nígbà tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, wọn kò tún ní ìkọminú mọ́ nípa ohun tí ó ṣẹlẹ̀. Wọ́n bá ń yin Ọlọrun. Wọ́n ní, “Èyí ni pé Ọlọrun ti fún àwọn orílẹ̀-èdè yòókù náà ní anfaani láti ronupiwada kí wọ́n lè ní ìyè.”

Ìjọ ní Antioku

19 Àwọn tí ó túká nígbà inúnibíni tí ó ṣẹlẹ̀ ní àkókò Stefanu dé Fonike ní Kipru ati Antioku. Wọn kò bá ẹnikẹ́ni sọ̀rọ̀ ìyìn rere àfi àwọn Juu nìkan.

20 Ṣugbọn nígbà tí àwọn kan ninu àwọn ará Kipru ati Kirene dé Antioku, wọ́n bá àwọn ará Giriki sọ̀rọ̀, wọ́n ń waasu Oluwa Jesu fún wọn.

21 Agbára Oluwa hàn ninu iṣẹ́ wọn. Ọpọlọpọ eniyan ni wọ́n gbàgbọ́, tí wọ́n sì yipada sí Oluwa.

22 Ìròyìn dé etí ìjọ tí ó wà ní Jerusalẹmu nípa wọn. Wọ́n bá rán Banaba sí Antioku.

23 Nígbà tí ó dé, tí ó rí bí Ọlọrun ti ṣiṣẹ́ láàrin wọn, inú rẹ̀ dùn. Ó gba gbogbo wọn níyànjú pé kí wọ́n fi gbogbo ọkàn wọn dúró ti Oluwa pẹlu òtítọ́.

24 Nítorí Banaba jẹ́ eniyan rere, tí ó kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, tí ó sì gbàgbọ́ tọkàntọkàn, ọ̀pọ̀ eniyan ni ó di onigbagbọ.

25 Banaba bá wá Paulu lọ sí Tasu.

26 Nígbà tí ó rí i, ó mú un wá sí Antioku; fún ọdún kan gbáko ni àwọn mejeeji fi wà pẹlu ìjọ, tí wọn ń kọ́ ọpọlọpọ eniyan lẹ́kọ̀ọ́. Ní Antioku ni a ti kọ́ pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Kristi ní “Kristẹni.”

27 Ní àkókò náà, àwọn wolii kan wá láti Jerusalẹmu sí Antioku.

28 Ọ̀kan ninu wọn tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Agabu bá dìde. Ẹ̀mí gbé e láti sọ pé ìyàn ńlá yóo mú ní gbogbo ayé. (Èyí ṣẹlẹ̀ ní ayé ọba Kilaudiu.)

29 Ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Kristi bá pinnu pé olukuluku àwọn yóo sa gbogbo agbára rẹ̀ láti fi nǹkan ranṣẹ sí àwọn onigbagbọ tí ó ń gbé Judia.

30 Wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n kó nǹkan rán Banaba ati Saulu sí wọn.

Categories
ÌṢE ÀWỌN APOSTELI

ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 12

Inúnibíni sí ìjọ

1 Ní àkókò náà Hẹrọdu ọba bẹ̀rẹ̀ sí ṣe inúnibíni sí àwọn kan ninu ìjọ.

2 Ó bẹ́ Jakọbu arakunrin Johanu lórí.

3 Nígbà tí ó rí i pé ó dùn mọ́ àwọn Juu, ó bá tún mú Peteru náà. Àkókò náà ni Àjọ̀dún Àìwúkàrà.

4 Ó bá mú Peteru ó tì í mọ́lé. Ó fi í lé àwọn ọ̀wọ́ ọmọ-ogun mẹrin lọ́wọ́ láti máa ṣọ́ ọ; (ọmọ-ogun mẹrin ni ó wà ní ọ̀wọ́ kọ̀ọ̀kan). Hẹrọdu fẹ́ mú Peteru wá siwaju gbogbo eniyan fún ìdájọ́ lẹ́yìn Àjọ̀dún Ìrékọjá.

5 Wọ́n bá sọ Peteru sẹ́wọ̀n, ṣugbọn gbogbo ìjọ ń fi tọkàntọkàn gbadura sí Ọlọrun nítorí rẹ̀.

Peteru Bọ́ lẹ́wọ̀n

6 Ní òru, mọ́jú ọjọ́ tí Hẹrọdu ìbá mú Peteru wá fún ìdájọ́, Peteru sùn láàrin àwọn ọmọ-ogun meji, wọ́n fi ẹ̀wọ̀n meji dè é; àwọn ọmọ-ogun kan sì tún wà lẹ́nu ọ̀nà, tí wọn ń ṣọ́nà.

7 Angẹli Oluwa kan bá yọ dé, ìmọ́lẹ̀ sì tàn ninu ilé náà. Angẹli náà bá rọra lu Peteru lẹ́gbẹ̀ẹ́, ó jí i, ó ní, “Dìde kíá.” Àwọn ẹ̀wọ̀n tí wọ́n fi de Peteru bá yọ bọ́ kúrò ní ọwọ́ rẹ̀,

8 Angẹli náà sọ fún un pé, “Di ìgbànú rẹ, sì wọ sálúbàtà rẹ.” Peteru bá ṣe bí angẹli náà ti wí. Angẹli yìí tún sọ fún un pé, “Da aṣọ rẹ bora, kí o máa tẹ̀lé mi.”

9 Ni Peteru bá tẹ̀lé e jáde. Kò mọ̀ pé òtítọ́ ni ohun tí ó ti ọwọ́ angẹli náà ṣẹlẹ̀, ó ṣebí àlá ni.

10 Wọ́n kọjá ẹ̀ṣọ́ kinni ati ekeji, wọ́n wá dé ẹnu ọ̀nà ńlá onírin tí ó jáde sinu ìlú. Fúnra ìlẹ̀kùn yìí ni ó ṣí sílẹ̀ fún wọn. Wọ́n bá jáde sí ojú ọ̀nà kan. Lójú kan náà, angẹli bá rá mọ́ Peteru lójú.

11 Ojú Peteru wá wálẹ̀. Ó ní, “Mo wá mọ̀ nítòótọ́ pé Oluwa ni ó rán angẹli rẹ̀ láti gbà mí lọ́wọ́ Hẹrọdu, ati láti yọ mí kúrò ninu ohun gbogbo tí àwọn Juu ti ń retí.”

12 Nígbà tí ó rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀, ó lọ sí ilé Maria ìyá Johanu tí àdàpè rẹ̀ ń jẹ́ Maku. Ọpọlọpọ eniyan ni ó péjọ sibẹ tí wọn ń gbadura.

13 Nígbà tí Peteru kan ìlẹ̀kùn tí ó wà lójúde, ọdọmọbinrin kan tí ń jẹ́ Roda wá láti ṣí i.

14 Nígbà tí ó gbọ́ ohùn Peteru, inú rẹ̀ dùn tóbẹ́ẹ̀ tí kò fi dúró ṣí ìlẹ̀kùn; ṣugbọn ó sáré lọ sinu ilé, ó lọ sọ pé Peteru wà lóde lẹ́nu ọ̀nà.

15 Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí bú u pé, “Orí rẹ dàrú!” Ṣugbọn ó ṣá tẹnumọ́ ọn pé bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ rí. Wọ́n wá sọ pé, “A jẹ́ pé angẹli rẹ̀ ni!”

16 Ṣugbọn Peteru tún ń kanlẹ̀kùn. Nígbà tí wọ́n ṣí i, tí wọ́n rí i, ẹnu yà wọ́n.

17 Ó bá fi ọwọ́ ṣe àmì sí wọn kí wọ́n dákẹ́; ó ròyìn fún wọn bí Oluwa ti ṣe mú òun jáde kúrò lẹ́wọ̀n. Ó ní kí wọn ròyìn ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún Jakọbu ati fún àwọn arakunrin yòókù. Ó bá jáde, ó lọ sí ibòmíràn.

18 Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, ìdààmú ńlá bá àwọn ọmọ-ogun. Wọn kò mọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí Peteru.

19 Hẹrọdu wá Peteru títí, ṣugbọn kò rí i. Lẹ́yìn tí ó ti wádìí lẹ́nu àwọn ẹ̀ṣọ́ tán, ó ní kí wọ́n pa wọ́n.

Ni Hẹrọdu bá kúrò ní Judia, ó lọ sí Kesaria, ó lọ gbé ibẹ̀ fún ìgbà díẹ̀.

Bí Hẹrọdu Ṣe Kú

20 Inú bí Hẹrọdu pupọ sí àwọn ará Tire ati Sidoni. Àwọn ará ìlú wọnyi bá fi ohùn ṣọ̀kan, wọ́n wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Wọ́n tu Bilasitu tíí ṣe ìjòyè ọba tí ó ń mójútó ààfin lójú, wọ́n ń bẹ̀bẹ̀ pé kí ọba má bínú sí àwọn nítorí láti ilé ọba ni wọ́n ti ń rí oúnjẹ jẹ.

21 Nígbà tí ó di ọjọ́ tí ọba dá fún wọn, Hẹrọdu yọ dé pẹlu aṣọ ìgúnwà rẹ̀, ó jókòó lórí ìtẹ́ rẹ̀. Ó wá bá àwọn eniyan náà sọ̀rọ̀.

22 Ni àwọn eniyan náà bá ń kígbe pé, “Ohùn Ọlọrun nìyí, kì í ṣe ti eniyan!”

23 Lẹsẹkẹsẹ angẹli Oluwa bá lù ú pa, nítorí kò fi ògo fún Ọlọrun. Ni ìdin bá jẹ ẹ́ pa.

24 Ọ̀rọ̀ Ọlọrun bẹ̀rẹ̀ sí fìdí múlẹ̀ sí i, ó sì túbọ̀ ń tàn káàkiri.

25 Nígbà tí Banaba ati Saulu parí iṣẹ́ tí a rán wọn, wọ́n pada láti Jerusalẹmu, wọ́n mú Johanu tí àpèlé rẹ̀ ń jẹ́ Maku lọ́wọ́.

Categories
ÌṢE ÀWỌN APOSTELI

ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 13

A Yan Banaba ati Saulu fún Iṣẹ́ Pataki

1 Àwọn wolii ati àwọn olùkọ́ wà ninu ìjọ tí ó wà ní Antioku. Ninu wọn ni Banaba ati Simeoni tí wọn ń pè ní Adúláwọ̀ wà, ati Lukiusi ará Kirene, ati Manaeni tí wọ́n jọ tọ́ dàgbà pẹlu Hẹrọdu baálẹ̀, ati Saulu.

2 Bí wọ́n ti jọ ń sin Oluwa, tí wọ́n ń gbààwẹ̀, Ẹ̀mí Mímọ́ sọ fún wọn pé, “Ẹ ya Banaba ati Saulu sọ́tọ̀ fún mi, fún iṣẹ́ pataki kan tí mo ti pè wọ́n fún.”

3 Lẹ́yìn tí wọ́n ti gbààwẹ̀, tí wọ́n sì gbadura, wọ́n gbé ọwọ́ lé wọn lórí, wọ́n sì ní kí wọ́n máa lọ.

Àwọn Òjíṣẹ́ Waasu ní Kipru

4 Lẹ́yìn tí Ẹ̀mí Mímọ́ ti fi iṣẹ́ lé àwọn mejeeji lọ́wọ́, wọ́n lọ sí Selesia. Láti ibẹ̀ wọ́n wọ ọkọ̀ ojú omi lọ sí Kipru.

5 Nígbà tí wọ́n dé Salami, wọ́n waasu ọ̀rọ̀ Ọlọrun ninu àwọn ilé ìpàdé àwọn Juu. Wọ́n mú Johanu lọ́wọ́ kí wọn lè máa rí i rán níṣẹ́.

6 Wọ́n la erékùṣù náà kọjá, wọ́n dé Pafọsi. Níbẹ̀ ni wọ́n rí ọkunrin Juu kan, tí ó ń pidán, tí ó fi ń tú àwọn eniyan jẹ. Orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ba-Jesu.

7 Ọkunrin yìí ń ṣiṣẹ́ lọ́dọ̀ gomina ilẹ̀ náà, tí ń jẹ́ Segiu Paulu. Gomina yìí jẹ́ olóye eniyan. Ó ranṣẹ pe Banaba ati Saulu nítorí ó fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọrun.

8 Ṣugbọn Elimasi, tí ìtumọ̀ orúkọ rẹ̀ jẹ́ onídán, takò wọ́n. Ó ń wá ọ̀nà láti yí ọkàn gomina pada kúrò ninu igbagbọ.

9 Ẹ̀mí Mímọ́ bá gbé Saulu, tí a tún ń pè ní Paulu. Ó tẹjú mọ́ onídán náà,

10 ó ní, “Ìwọ yìí, tí ó jẹ́ kìkì oríṣìíríṣìí ẹ̀tàn ati ìwà burúkú! Ìwọ ọmọ èṣù yìí! Ọ̀tá gbogbo nǹkan tí ó dára! O kò ní yé yí ọ̀nà títọ́ Oluwa po!

11 Ọwọ́ Oluwa tẹ̀ ọ́ nisinsinyii. Ojú rẹ yóo fọ́, o kò ní lè rí oòrùn fún ìgbà kan!”

Lójú kan náà, ìkùukùu dúdú dà bò ó. Ó bá ń tá ràrà, ó ń wá ẹni tí yóo fà á lọ́wọ́ kiri.

12 Nígbà tí gomina rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀, ó gbàgbọ́; nítorí pé ẹ̀kọ́ nípa Oluwa yà á lẹ́nu.

Paulu ati Banaba Lọ sí Antioku Ilẹ̀ Pisidia

13 Nígbà tí Paulu ati àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ kúrò ní Pafọsi, wọ́n wọ ọkọ̀ ojú omi lọ sí ìlú Pega ní ilẹ̀ Pamfilia. Johanu fi wọ́n sílẹ̀ níbẹ̀, ó pada lọ sí Jerusalẹmu.

14 Wọ́n la ilẹ̀ náà kọjá láti Pega títí wọ́n fi dé ìlú Antioku lẹ́bàá ilẹ̀ Pisidia. Wọ́n lọ sí ilé ìpàdé àwọn Juu ní Ọjọ́ Ìsinmi, wọ́n bá jókòó.

15 Lẹ́yìn tí wọ́n ti ka Ìwé Mímọ́, láti inú Ìwé Òfin Mose ati Ìwé àwọn wolii, àwọn olóyè ilé ìpàdé àwọn Juu sọ fún wọn pé, “Ẹ̀yin arakunrin, bí ẹ bá ní ọ̀rọ̀ ìyànjú fún àwọn eniyan, ẹ sọ ọ́.”

16 Ni Paulu bá dìde, ó gbé ọwọ́ sókè, ó ní:

“Ẹ̀yin ọmọ Israẹli ati ẹ̀yin tí ẹ̀ ń sin Ọlọrun wa, ẹ fetí sílẹ̀.

17 Ọlọrun àwọn eniyan yìí, eniyan Israẹli, yan àwọn baba wa. Nígbà tí wọn ń gbé ilẹ̀ Ijipti bí àlejò, Ọlọrun sọ wọ́n di eniyan ńlá. Ó fi agbára ńlá rẹ̀ hàn nígbà tí ó mú wọn jáde kúrò ní Ijipti.

18 Fún nǹkan bí ogoji ọdún ni ó fi ń kẹ́wọn ní aṣálẹ̀.

19 Orílẹ̀-èdè meje ni ó parẹ́ ní ilẹ̀ Kenaani nítorí tiwọn, ó sì jẹ́ kí wọ́n jogún ilẹ̀ wọn,

20 fún nǹkan bí irinwo ọdún ó lé aadọta (450).

“Lẹ́yìn èyí ó fún wọn ní àwọn onídàájọ́ títí di àkókò wolii Samuẹli.

21 Lẹ́yìn náà wọ́n bèèrè fún ọba; Ọlọrun bá fún wọn ní Saulu ọmọ Kiṣi, láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini. Ó jọba fún ogoji ọdún.

22 Nígbà tí Ọlọrun yọ ọ́ lóyè, ó gbé Dafidi dìde fún wọn bí ọba. Ọlọrun jẹ́rìí sí ìwà rẹ̀ nígbà tí ó sọ pé, ‘Mo rí i pé Dafidi ọmọ Jese jẹ́ ẹni tí ọkàn mi ń fẹ́, ẹni tí yóo ṣe ohun gbogbo bí mo ti fẹ́.’

23 Láti inú ìran rẹ̀ ni Ọlọrun ti gbé Jesu dìde bí Olùgbàlà fún Israẹli gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ìlérí.

24 Kí Jesu tó yọjú, Johanu ti ń waasu fún gbogbo àwọn eniyan Israẹli pé kí wọ́n ṣe ìrìbọmi bí àmì pé wọ́n ronupiwada.

25 Nígbà tí Johanu fẹ́rẹ̀ dópin iṣẹ́ rẹ̀, ó ní, ‘Ta ni ẹ rò pé mo jẹ́? Èmi kì í ṣe ẹni tí ẹ rò. Ẹnìkan ń bọ̀ lẹ́yìn mi, ẹni tí n kò tó tú okùn bàtà ẹsẹ̀ rẹ̀.’

26 “Ẹ̀yin arakunrin, ìran Abrahamu, ati ẹ̀yin tí ẹ̀ ń sin Ọlọrun, àwa ni a rán iṣẹ́ ìgbàlà yìí sí.

27 Àwọn tí ó ń gbé Jerusalẹmu ati àwọn olóyè wọn, wọn kò mọ ẹni tí Jesu jẹ́, bẹ́ẹ̀ ni ohun tí àwọn wolii ń sọ kò yé wọn bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ ni wọ́n ń kà á. Wọ́n mú àkọsílẹ̀ wọnyi ṣẹ nígbà tí wọ́n dá a lẹ́bi ikú.

28 Láìjẹ́ pé wọ́n rí ohunkohun tí ó fi jẹ̀bi ikú, wọ́n ní kí Pilatu pa á.

29 Nígbà tí wọ́n ti parí ohun gbogbo tí ó wà ní àkọsílẹ̀ pé yóo ṣẹlẹ̀ sí i, wọ́n sọ̀ ọ́ kalẹ̀ láti orí igi agbelebu, wọ́n tẹ́ ẹ sinu ibojì.

30 Ṣugbọn Ọlọrun jí i dìde kúrò ninu òkú.

31 Fún ọpọlọpọ ọjọ́ ni ó fi ara hàn fún àwọn tí wọ́n bá a wá sí Jerusalẹmu láti Galili. Àwọn ni ẹlẹ́rìí fún gbogbo eniyan pé bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ rí.

32-33 A wá mú ìyìn rere wá fun yín pé ìlérí tí Ọlọrun ṣe fún àwọn baba wa ti ṣẹ, fún àwọn ọmọ wa, nígbà tí ó jí Jesu dìde, gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀ ninu Orin Dafidi keji pé,

‘Ọmọ mi ni ọ́, lónìí yìí ni mo bí ọ.’

34 Ní ti pé ó jí i dìde kúrò ninu òkú, tí kò pada sí ipò ìdíbàjẹ́ mọ́, ohun tí ó sọ ni pé,

‘Èmi yóo fun yín ní ohun tí mo bá Dafidi pinnu.’

35 Bẹ́ẹ̀ ni ó tún sọ níbòmíràn pé,

‘O kò ní jẹ́ kí Ẹni ọ̀wọ̀ rẹ mọ ìdíbàjẹ́.’

36 Nítorí nígbà tí Dafidi ti sin ìran tirẹ̀ tán gẹ́gẹ́ bí ète Ọlọrun, ó sun oorun ikú, ó lọ bá àwọn baba rẹ̀, ara rẹ̀ rà nílẹ̀.

37 Ṣugbọn ẹni tí Ọlọrun jí dìde kò ní ìrírí ìdíbàjẹ́.

38-39 Nítorí náà, ẹ̀yin ará, kí ó hàn si yín pé nítorí ẹni yìí ni a ṣe ń waasu ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ fun yín. Ọpẹ́lọpẹ́ ẹni yìí ni a fi dá gbogbo ẹni tí ó bá gbàgbọ́ láre, àwọn tí Òfin Mose kò lè dá láre.

40 Nítorí náà, ẹ ṣọ́ra kí ohun tí a kọ sílẹ̀ ninu ìwé àwọn wolii má baà dé ba yín:

41 ‘Ẹ wò ó, ẹ̀yin ẹlẹ́gàn, kí ó yà yín lẹ́nu, kí ẹ sì parun!

Nítorí n óo ṣe iṣẹ́ kan ní àkókò yín,

tí ẹ kò ní gbàgbọ́ bí ẹnìkan bá ròyìn rẹ̀ fun yín.’ ”

42 Bí Paulu ati Banaba ti ń jáde lọ, bẹ́ẹ̀ ni àwọn eniyan ń bẹ̀ wọ́n pé kí wọ́n tún pada wá bá wọn sọ irú ọ̀rọ̀ yìí ní ọ̀sẹ̀ tí ó ń bọ̀.

43 Nígbà tí ìpàdé túká, ọpọlọpọ àwọn Juu ati àwọn tí wọ́n ti di ẹlẹ́sìn àwọn Juu ń tẹ̀lé Paulu ati Banaba. Àwọn òjíṣẹ́ mejeeji yìí tún ń bá wọn sọ̀rọ̀, wọ́n ń gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n dúró láì yẹsẹ̀ ninu oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun.

44 Nígbà tí ó di Ọjọ́ Ìsinmi keji, ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ pé gbogbo ìlú ni ó péjọ láti gbọ́ ọ̀rọ̀ Oluwa.

45 Nígbà tí àwọn Juu rí ọ̀pọ̀ eniyan, owú mú kí inú bí wọn. Wọ́n bá ń bu ẹnu àtẹ́ lu ohun tí Paulu ń sọ; wọ́n ń sọ ìsọkúsọ sí wọn.

46 Paulu ati Banaba wá fi ìgboyà sọ pé, “Ẹ̀yin ni a níláti kọ́ sọ ọ̀rọ̀ Ọlọrun fún. Ṣugbọn nígbà tí ẹ kọ̀ ọ́, tí ẹ kò ka ara yín yẹ fún ìyè ainipẹkun, àwa ń lọ sọ́dọ̀ àwọn tí kì í ṣe Juu.

47 Nítorí bẹ́ẹ̀ ni Oluwa pa láṣẹ fún wa nígbà tí ó sọ pé:

‘Mo ti fi ọ́ ṣe ìmọ́lẹ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè yòókù,

kí ìgbàlà mi lè dé òpin ilẹ̀ ayé.’ ”

48 Nígbà tí àwọn tí kì í ṣe Juu gbọ́, inú wọn dùn. Wọ́n dúpẹ́ fún ọ̀rọ̀ Oluwa. Gbogbo àwọn tí a ti yàn láti ní ìyè ainipẹkun bá gbàgbọ́.

49 Ọ̀rọ̀ Oluwa tàn ká gbogbo ilẹ̀ náà.

50 Ṣugbọn àwọn Juu rú àwọn gbajúmọ̀ obinrin olùfọkànsìn sókè, ati àwọn eniyan pataki-pataki ní ìlú, ni wọ́n bá ń ṣe inúnibíni sí Paulu ati Banaba. Wọ́n lé wọn jáde kúrò ní agbègbè wọn.

51 Ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn náà bá gbọn eruku ẹsẹ̀ wọn sílẹ̀ bí ẹ̀rí sí àwọn ará ìlú náà, wọ́n bá lọ sí Ikoniomu.

52 Ayọ̀ kún ọkàn àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu. Bẹ́ẹ̀ ni Ẹ̀mí Mímọ́ sì kún inú wọn.

Categories
ÌṢE ÀWỌN APOSTELI

ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 14

Iṣẹ́ Paulu ati Banaba ní Ikoniomu

1 Nígbà tí wọ́n dé Ikoniomu, wọ́n lọ sí ilé ìpàdé àwọn Juu gẹ́gẹ́ bí ìṣe wọn. Wọ́n sọ̀rọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ọpọlọpọ ninu àwọn Juu ati àwọn Giriki fi gba Jesu gbọ́.

2 Àwọn Juu tí kò gbà pé Jesu ni Mesaya wá gbin èrò burúkú sí ọkàn àwọn tí kì í ṣe Juu, wọ́n rú wọn sókè sí àwọn onigbagbọ.

3 Paulu ati Banaba pẹ́ níbẹ̀. Wọ́n ń sọ̀rọ̀ ní gbangba, ẹ̀rù kò sì bà wọ́n nítorí wọ́n gbójú lé Oluwa tí ó jẹ́rìí sí ọ̀rọ̀ oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ nípa iṣẹ́ abàmì ati iṣẹ́ ìyanu tí ó ń ti ọwọ́ wọn ṣe.

4 Ìyapa bẹ́ sáàrin àwọn eniyan ninu ìlú; àwọn mìíràn fara mọ́ àwọn Juu, àwọn mìíràn fara mọ́ àwọn aposteli.

5 Àwọn Juu ati àwọn tí kì í ṣe Juu pẹlu àwọn ìjòyè wọn dábàá láti ṣe wọ́n lọ́ṣẹ́, wọ́n fẹ́ sọ wọ́n ní òkúta pa.

6 Nígbà tí àwọn aposteli mọ̀, wọ́n sálọ sí Listira ati Dabe, ìlú meji ní Likaonia, ati àwọn agbègbè wọn.

7 Wọ́n bá ń waasu ìyìn rere níbẹ̀.

Iṣẹ́ Paulu ati Banaba ní Listira

8 Ọkunrin kan wà ní ìjókòó ní Listira tí ó yarọ. Láti ìgbà tí wọ́n ti bí i ni ó ti yarọ, kò fi ẹsẹ̀ rẹ̀ rìn rí.

9 Ọkunrin yìí fetí sílẹ̀ bí Paulu ti ń sọ̀rọ̀. Paulu wá tẹjú mọ́ ọn lára, ó rí i pé ó ní igbagbọ pé wọ́n lè mú òun lára dá.

10 Ó bá kígbe sókè, ó ní, “Dìde, kí o dúró lórí ẹsẹ̀ rẹ bí eniyan.” Ni ọkunrin arọ náà bá fò sókè, ó bá ń rìn.

11 Nígbà tí àwọn eniyan rí ohun tí Paulu ṣe, wọ́n kígbe ní èdè Likaonia pé, “Àwọn oriṣa ti di eniyan, wọ́n tọ̀run wá sáàrin wa!”

12 Wọ́n pe Banaba ní Seusi, wọ́n pe Paulu ní Herime nítorí òun ni ó ń ṣe ògbifọ̀.

13 Ní òde kí á tó wọ odi ìlú ni tẹmpili Seusi wà. Baba olórìṣà Seusi bá mú mààlúù ati òdòdó jìngbìnnì, òun ati ọpọlọpọ èrò, wọ́n ń bọ̀ lẹ́nu odi ìlú níbi tí pẹpẹ Seusi wà, wọ́n fẹ́ wá bọ wọ́n.

14 Nígbà tí Banaba aposteli ati Paulu aposteli gbọ́, wọ́n fa ẹ̀wù wọn ya, wọ́n bá pa kuuru mọ́ àwọn èrò, wọ́n ń kígbe pé,

15 “Ẹ̀yin eniyan, kí ló dé tí ẹ fi ń ṣe irú eléyìí? Eniyan bíi yín ni àwa náà. À ń waasu fun yín pé kí ẹ yipada kúrò ninu àwọn ohun asán wọnyi, kí ẹ sin Ọlọrun alààyè, ẹni tí ó dá ọ̀run ati ayé, ati òkun ati ohun gbogbo tí ó wà ninu wọn.

16 Ní ìgbà ayé àwọn tí ó ti kọjá, ó jẹ́ kí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè máa ṣe ohun tí ó wù wọ́n.

17 Sibẹ kò ṣàì fi àmì ara rẹ̀ hàn: ó ń ṣe iṣẹ́ rere, ó ń rọ òjò fun yín láti ọ̀run, ó ń mú èso jáde lásìkò, ó ń fun yín ní oúnjẹ, ó tún ń mú inú yín dùn.”

18 Pẹlu gbogbo ọ̀rọ̀ yìí, agbára-káká ni wọn kò fi jẹ́ kí àwọn eniyan bọ wọ́n.

19 Ṣugbọn àwọn Juu dé láti Antioku ati Ikoniomu, wọ́n yí ọkàn àwọn eniyan pada, wọ́n sọ Paulu ní òkúta, wọ́n sì wọ́ ọ lọ sẹ́yìn odi, wọ́n ṣebí ó ti kú.

20 Ṣugbọn àwọn onigbagbọ pagbo yí i ká títí ó fi dìde tí ó sì wọ inú ìlú lọ. Ní ọjọ́ keji ó gbéra lọ sí Dabe pẹlu Banaba.

Paulu ati Banaba Pada lọ sí Antioku ní Siria

21 Wọ́n waasu ìyìn rere ní ìlú náà, àwọn eniyan pupọ sì di onigbagbọ. Wọ́n bá pada sí Listira ati Ikoniomu ati Antioku ní Pisidia.

22 Wọ́n ń mú àwọn onigbagbọ lọ́kàn le pé kí wọ́n dúró ṣinṣin ninu igbagbọ. Wọ́n ń fi yé wọn pé kí eniyan tó wọ ìjọba Ọlọrun, ó níláti ní ọpọlọpọ ìṣòro.

23 Wọ́n yan àgbà ìjọ fún wọn ninu ìjọ kọ̀ọ̀kan. Nígbà tí wọ́n ti gbadura, tí wọ́n sì ti gbààwẹ̀, wọ́n fi wọ́n lé ọwọ́ Oluwa tí wọ́n gbẹ́kẹ̀ wọn lé.

24 Wọ́n wá gba Pisidia kọjá lọ sí Pamfilia.

25 Nígbà tí wọ́n ti waasu ìyìn rere ní Pega, wọ́n lọ sébùúté ní Atalia.

26 Wọ́n wọ ọkọ̀ ojú omi láti ibẹ̀ lọ sí Antioku ní Siria níbi tí wọ́n ti kọ́ fi wọ́n sábẹ́ ojurere Ọlọrun fún iṣẹ́ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ parí.

27 Nígbà tí wọ́n dé ibẹ̀, wọ́n pe gbogbo ìjọ jọ, wọ́n ròyìn ohun gbogbo tí Ọlọrun tọwọ́ wọn ṣe ati bí Ọlọrun ti ṣínà fún àwọn tí kì í ṣe Juu láti gbàgbọ́.

28 Wọ́n dúró níbẹ̀ lọ́dọ̀ àwọn onigbagbọ fún ìgbà pípẹ́.

Categories
ÌṢE ÀWỌN APOSTELI

ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 15

Ìgbìmọ̀ Ìjọ Jerusalẹmu

1 Àwọn kan wá láti Judia tí wọn ń kọ́ àwọn onigbagbọ pé, “Bí ẹ kò bá kọlà gẹ́gẹ́ bí àṣà ati Òfin Mose, a kò lè gbà yín là!”

2 Ó di ọ̀rọ̀ líle ati àríyànjiyàn ńlá láàrin àwọn ati Paulu ati Banaba. Ni ìjọ bá pinnu pé kí Paulu ati Banaba ati àwọn mìíràn láàrin wọn lọ sọ́dọ̀ àwọn aposteli ati àwọn alàgbà ní Jerusalẹmu láti yanjú ọ̀rọ̀ náà.

3 Àwọn ìjọ sìn wọ́n sọ́nà, wọ́n wá gba Fonike ati Samaria kọjá, wọ́n ń ròyìn gẹ́gẹ́ bí àwọn tí kì í ṣe Juu ṣe ń yipada di onigbagbọ. Èyí mú kí inú gbogbo àwọn onigbagbọ tí wọ́n gbọ́ dùn pupọ.

4 Nígbà tí wọ́n dé Jerusalẹmu, gbogbo ìjọ, ati àwọn aposteli ati àwọn àgbààgbà gbà wọ́n tọwọ́-tẹsẹ̀. Wọ́n wá ròyìn ohun gbogbo tí Ọlọrun ti ṣe fún wọ́n.

5 Àwọn kan láti inú ẹgbẹ́ àwọn Farisi tí wọ́n jẹ́ onigbagbọ wá dìde. Wọ́n ní, “Dandan ni pé kí á kọ àwọn tí kì í ṣe Juu tí ó bá fẹ́ di onigbagbọ nílà, kí á sì pàṣẹ fún wọn láti máa pa Òfin Mose mọ́.”

6 Gbogbo àwọn aposteli ati àwọn àgbààgbà bá péjọ láti rí sí ọ̀rọ̀ yìí.

7 Àríyànjiyàn pupọ ni ó bẹ́ sílẹ̀ láàrin wọn. Peteru bá dìde, ó ní, “Ẹ̀yin arakunrin, ẹ̀yin gan-an mọ̀ pé ní àtijọ́ Ọlọrun yàn mí láàrin yín pé láti ẹnu mi ni àwọn tí kì í ṣe Juu yóo ti gbọ́ ọ̀rọ̀ ìyìn rere, kí wọ́n lè gba Jesu gbọ́.

8 Ọlọrun olùmọ̀ràn ọkàn fún wọn ní ìwé ẹ̀rí nígbà tí ó fún wọn ní Ẹ̀mí Mímọ́ gẹ́gẹ́ bí ó ti fún wa.

9 Kò fi ìyàtọ̀ kankan sáàrin àwa ati àwọn; ó wẹ ọkàn wọn mọ́ nítorí wọ́n gba Jesu gbọ́.

10 Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, kí ní ṣe tí ẹ fi fẹ́ dán Ọlọrun wò, tí ẹ fẹ́ gbé àjàgà tí àwọn baba wa ati àwa náà kò tó rù, rù àwọn ọmọ-ẹ̀yìn?

11 A gbàgbọ́ pé nípa oore-ọ̀fẹ́ Jesu Oluwa ni a fi gbà wá là, gẹ́gẹ́ bí a ti fi gba àwọn náà là.”

12 Ńṣe ni gbogbo àwùjọ dákẹ́ jẹ́ẹ́. Wọ́n wá fetí sílẹ̀ sí ohun tí Banaba ati Paulu níí sọ nípa iṣẹ́ abàmì ati iṣẹ́ ìyanu tí Ọlọrun tọwọ́ wọn ṣe láàrin àwọn tí kì í ṣe Juu.

13 Lẹ́yìn tí wọ́n ti parí ọ̀rọ̀ tí wọ́n níí sọ, Jakọbu bá fèsì pé, “Ẹ̀yin arakunrin, ẹ fetí sí mi.

14 Simoni ti ròyìn ọ̀nà tí Ọlọrun kọ́kọ́ fi ṣe ìkẹ́ àwọn tí kì í ṣe Juu kí ó lè mú ninu wọn fi ṣe eniyan tirẹ̀.

15 Ọ̀rọ̀ àwọn wolii bá èyí mu, gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀ pé,

16 ‘Lẹ́yìn èyí, n óo tún ilé Dafidi tí ó ti wó kọ́.

N óo tún ahoro rẹ̀ mọ,

n óo sì gbé e ró.

17 Báyìí ni gbogbo àwọn tí kì í ṣe Juu yóo máa wá Oluwa,

ati gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn tí mo ti pè láti jẹ́ tèmi.

18 Bẹ́ẹ̀ ni Oluwa wí,

ó sì jẹ́ kí á mọ ọ̀rọ̀ náà láti ìgbà àtijọ́-tijọ́.’

19 “Ní tèmi, èrò mi ni pé kí á má tún yọ àwọn tí kì í ṣe Juu tí wọ́n yipada sí Ọlọrun lẹ́nu mọ́.

20 Kàkà bẹ́ẹ̀ kí á kọ ìwé sí wọn pé kí wọ́n takété sí ohunkohun tí ó bá ti di àìmọ́ nítorí pé a ti fi rúbọ sí oriṣa; kí wọn má ṣe àgbèrè, kí wọn má jẹ ẹran tí a lọ́ lọ́rùn pa, kí wọn má sì jẹ ẹ̀jẹ̀.

21 Nítorí láti ìgbà àtijọ́ ni wọ́n ti ń ké òkìkí Mose láti ìlú dé ìlú tí wọn sì ń ka ìwé rẹ̀ ninu gbogbo ilé ìpàdé lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀.”

Ìpinnu ìgbìmọ̀

22 Àwọn aposteli ati àwọn àgbà ìjọ pẹlu gbogbo ìjọ wá pinnu láti yan àwọn eniyan láàrin wọn, láti rán lọ sí Antioku pẹlu Paulu ati Banaba. Wọ́n bá yan Juda tí à ń pè ní Basaba ati Sila, tí wọn jẹ́ aṣaaju láàrin àwọn onigbagbọ.

23 Wọ́n fi ìwé rán wọn, pé:

“Àwa aposteli ati àwa alàgbà kí ẹ̀yin tí kì í ṣe Juu ní Antioku, Siria ati Silisia; a kí yín bí arakunrin sí arakunrin.

24 A gbọ́ pé àwọn kan láti ọ̀dọ̀ wa ń fi ọ̀rọ̀ yọ yín lẹ́nu, wọn kò jẹ́ kí ọkàn yín balẹ̀. A kò rán wọn níṣẹ́.

25 A ti wá pinnu, gbogbo wa sì fohùn sí i, a wá yan àwọn eniyan láti rán si yín pẹlu Banaba ati Paulu, àwọn àyànfẹ́ wa,

26 àwọn tí wọ́n ti fi ẹ̀mí wọn lélẹ̀ nítorí orúkọ Oluwa wa Jesu Kristi.

27 Nítorí náà a rán Juda ati Sila, láti fẹnu sọ ohun kan náà tí a kọ sinu ìwé fun yín.

28 Ẹ̀mí Mímọ́ ati àwa náà pinnu pé kí á má tún di ẹrù tí ó wúwo jù le yín lórí mọ́, yàtọ̀ sí àwọn nǹkan pataki wọnyi:

29 kí ẹ má jẹ ẹran tí a fi rúbọ sí oriṣa; kí ẹ má jẹ ẹ̀jẹ̀; kí ẹ má jẹ ẹran tí a lọ́ lọ́rùn pa; kí ẹ má ṣe àgbèrè.Bí ẹ bá takété sí àwọn nǹkan wọnyi, yóo dára. Ó dìgbà o!”

30 Nígbà tí àwọn tí a rán kúrò, wọ́n dé Antioku, wọ́n pe gbogbo ìjọ, wọ́n fún wọn ní ìwé náà.

31 Nígbà tí wọ́n kà á, inú wọn dùn sí ọ̀rọ̀ ìyànjú tí ó wà ninu rẹ̀.

32 Juda ati Sila, tí wọ́n jẹ́ wolii fúnra wọn, tún fi ọpọlọpọ ọ̀rọ̀ gba ẹgbẹ́ onigbagbọ náà níyànjú, wọ́n tún mú wọn lọ́kàn le.

33 Wọ́n dúró fún ìgbà díẹ̀, ni àwọn ìjọ bá fi tayọ̀tayọ̀ rán wọn pada lọ sọ́dọ̀ àwọn tí ó rán wọn wá. [

34 Ṣugbọn Sila pinnu láti dúró níbẹ̀.]

35 Ṣugbọn Paulu ati Banaba dúró ní Antioku, wọ́n ń kọ́ àwọn eniyan, àwọn ati eniyan pupọ mìíràn ń waasu ọ̀rọ̀ Oluwa.

Paulu ati Banaba Gba Ọ̀nà Ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀

36 Lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀ Paulu wí fún Banaba pé, “Jẹ́ kí á pada lọ bẹ àwọn onigbagbọ wò ní gbogbo ìlú tí a ti waasu ọ̀rọ̀ Oluwa, kí a rí bí wọ́n ti ń ṣe.”

37 Banaba fẹ́ mú Johanu tí à ń pè ní Maku lọ.

38 Ṣugbọn Paulu kò rò pé ó yẹ láti mú un lọ, nítorí ó pada lẹ́yìn wọn ní Pamfilia, kò bá wọn lọ títí dé òpin iṣẹ́ náà.

39 Àríyànjiyàn náà le tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi pínyà, tí olukuluku fi bá ọ̀nà rẹ̀ lọ. Banaba mú Maku, wọ́n wọ ọkọ̀ ojú omi lọ sí Kipru.

40 Paulu mú Sila ó bá ọ̀nà tirẹ̀ lọ lẹ́yìn tí àwọn onigbagbọ ti fi í lé oore-ọ̀fẹ́ Oluwa lọ́wọ́.

41 Ó gba Siria ati Silisia kọjá, ó ń mú àwọn ìjọ lọ́kàn le.

Categories
ÌṢE ÀWỌN APOSTELI

ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 16

Timoti ba Paulu ati Sila lọ

1 Paulu dé Dabe ati Listira. Onigbagbọ kan tí ń jẹ́ Timoti wà níbẹ̀. Ìyá rẹ̀ jẹ́ Juu tí ó gba Jesu gbọ́; ṣugbọn Giriki ni baba rẹ̀.

2 Àwọn arakunrin ní Listira ati Ikoniomu ròyìn Timoti yìí dáradára.

3 Òun ni ó wu Paulu láti mú lọ sí ìrìn-àjò rẹ̀, nítorí náà, ó mú un, ó kọ ọ́ nílà nítorí àwọn Juu tí ó wà ní agbègbè ibẹ̀; nítorí gbogbo wọn ni wọ́n mọ̀ pé Giriki ni baba rẹ̀.

4 Bí wọ́n ti ń lọ láti ìlú dé ìlú, wọ́n ń sọ fún wọn nípa ìpinnu tí àwọn aposteli ati àwọn àgbààgbà ní Jerusalẹmu ṣe, wọ́n sì ń gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n pa wọ́n mọ́.

5 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ìjọ túbọ̀ ń lágbára sí i ninu igbagbọ, tí wọ́n sì ń pọ̀ sí i ní iye lojoojumọ.

Paulu Rí Ará Masedonia Kan ní Ojú Ìran

6 Wọ́n gba ilẹ̀ Firigia ati Galatia kọjá. Ẹ̀mí Mímọ́ kò gbà wọ́n láàyè láti lọ waasu ọ̀rọ̀ Oluwa ní Esia.

7 Nígbà tí wọ́n súnmọ́ Misia, wọ́n gbìyànjú láti lọ sí Bitinia. Ṣugbọn Ẹ̀mí Jesu kò gbà fún wọn.

8 Nígbà tí wọ́n ti la Misia kọjá, wọ́n dé Tiroasi.

9 Nígbà tí ó di alẹ́, Paulu rí ìran kan. Ó rí ọkunrin kan ará Masedonia tí ó dúró, tí ó ń bẹ̀ ẹ́ pé, “Sọdá sí Masedonia níbí kí o wá ràn wá lọ́wọ́.”

10 Gbàrà tí ó rí ìran náà, a wá ọ̀nà láti lọ sí Masedonia; a pinnu pé Ọlọrun ni ó pè wá láti lọ waasu fún wọn níbẹ̀.

Lidia di Onigbagbọ

11 Nígbà tí a wọ ọkọ̀ láti Tiroasi, a lọ tààrà sí Samotirake. Ní ọjọ́ keji a gúnlẹ̀ ní Neapoli.

12 Láti ibẹ̀, a lọ sí Filipi tíí ṣe olú-ìlú ilẹ̀ Masedonia. Àwọn ará Romu ni wọ́n tẹ ìlú yìí dó. A bá wà níbẹ̀ fún ọjọ́ mélòó kan.

13 Ní Ọjọ́ Ìsinmi a jáde lọ sẹ́yìn odi ìlú lẹ́bàá odò, níbi tí a rò pé a óo ti rí ibi tí wọn máa ń gbadura. A bá jókòó, a bá àwọn obinrin tí ó péjọ níbẹ̀ sọ̀rọ̀.

14 Obinrin kan wà níbẹ̀ tí ó ń jẹ́ Lidia, ará Tiatira, tí ó ń ta aṣọ àlàárì. Ó jẹ́ ẹnìkan tí ó ń sin Ọlọrun. Ó fetí sílẹ̀, Ọlọrun ṣí i lọ́kàn láti gba ohun tí Paulu ń sọ.

15 Òun ati àwọn ará ilé rẹ̀ gba ìrìbọmi. Lẹ́yìn náà, ó bẹ̀ wá pé, bí a bá gbà pé òun jẹ́ onigbagbọ nítòótọ́, kí á máa bọ̀ ní ilé òun kí á máa bá àwọn gbé. Ó tẹnu mọ́ ọn títí a fi gbà.

Wọ́n Ju Paulu ati Sila sẹ́wọ̀n ní Filipi

16 Ní ọjọ́ kan, bí a ti ń lọ sí ibi adura, a pàdé ọdọmọbinrin kan tí ó ní ẹ̀mí àfọ̀ṣẹ. Ó ti ń mú èrè pupọ wá fún àwọn olówó rẹ̀ nípa àfọ̀ṣẹ rẹ̀.

17 Ó ń tẹ̀lé Paulu ati àwa náà, ó ń kígbe pé, “Àwọn ọkunrin yìí ni iranṣẹ Ọlọrun Ọ̀gá Ògo; àwọn ni wọ́n ń waasu ọ̀nà ìgbàlà fun yín.”

18 Ó ń ṣe báyìí fún ọjọ́ pupọ. Nígbà tí ara Paulu kò gbà á mọ́, ó yipada, ó sọ fún ẹ̀mí náà pé, “Mo pàṣẹ fún ọ ní orúkọ Jesu, jáde kúrò ninu rẹ̀.” Ni ó bá jáde lẹ́sẹ̀ kan náà.

19 Nígbà tí àwọn olówó ọdọmọbinrin náà rí i pé ọ̀nà oúnjẹ wọ́n ti dí, wọ́n ki Paulu ati Sila mọ́lẹ̀, wọ́n fà wọ́n lọ sọ́dọ̀ àwọn aláṣẹ ní ọjà.

20 Wọ́n mú wọn wá siwaju àwọn adájọ́. Wọ́n ní, “Juu ni àwọn ọkunrin wọnyi, wọ́n sì ń da ìlú wa rú.

21 Wọ́n ń kọ́ àwọn eniyan ní àṣà tí kò tọ́ fún wa láti gbà tabi láti ṣe nítorí ará Romu ni wá.”

22 Ni àwọn eniyan bá bẹ̀rẹ̀ sí lu Paulu ati Sila.

Àwọn adájọ́ fa aṣọ ya mọ́ wọn lára, wọ́n pàṣẹ pé kí wọ́n nà wọ́n.

23 Nígbà tí wọ́n ti nà wọ́n dáradára, wọ́n bá sọ wọ́n sẹ́wọ̀n. Wọ́n pàṣẹ fún ẹni tí ó ń ṣọ́ àwọn ẹlẹ́wọ̀n pé kí ó ṣọ́ wọn dáradára.

24 Nígbà tí ó ti gba irú àṣẹ báyìí, ó sọ wọ́n sinu àtìmọ́lé ti inú patapata, ó tún fi ààbà kan ẹsẹ̀ wọn mọ́ igi.

25 Nígbà tí ó di ọ̀gànjọ́, Paulu ati Sila ń gbadura, wọ́n ń kọrin sí Ọlọrun. Àwọn ẹlẹ́wọ̀n yòókù ń dẹtí sí wọn.

26 Lójijì ni ilẹ̀ mì tìtì, tóbẹ́ẹ̀ tí ìpìlẹ̀ ilé ẹ̀wọ̀n mì. Lọ́gán gbogbo ìlẹ̀kùn ṣí; gbogbo ẹ̀wọ̀n tí a fi de àwọn ẹlẹ́wọ̀n sì tú.

27 Nígbà tí ẹni tí ó ń ṣọ́ ilé ẹ̀wọ̀n jí lójú oorun, tí ó rí i pé ìlẹ̀kùn ilé ẹ̀wọ̀n ti ṣí, ó fa idà rẹ̀ yọ, ó fẹ́ pa ara rẹ̀, ó ṣebí àwọn ẹlẹ́wọ̀n ti sálọ ni.

28 Paulu bá kígbe pè é, ó ní, “Má ṣe ara rẹ léṣe, nítorí gbogbo wa wà níhìn-ín.”

29 Ẹni tí ń ṣọ́ ilé ẹ̀wọ̀n náà bá bèèrè iná, ó pa kuuru wọ inú iyàrá, ó ń gbọ̀n láti orí dé ẹsẹ̀. Ó wólẹ̀ níwájú Paulu ati Sila.

30 Ó mú wọn jáde, ó ní, “Ẹ̀yin alàgbà, kí ni ó yẹ kí n ṣe kí n lè là?”

31 Wọ́n dá a lóhùn pé, “Gba Jesu Oluwa gbọ́, ìwọ ati ìdílé rẹ yóo sì là.”

32 Wọ́n bá sọ ọ̀rọ̀ Oluwa fún òun ati gbogbo ìdílé rẹ̀.

33 Ní òru náà, ó mú wọn, ó wẹ ọgbẹ́ wọn. Lójú kan náà òun ati gbogbo ìdílé rẹ̀ sì ṣe ìrìbọmi.

34 Ó bá mú wọn wọ ilé, ó fún wọn ní oúnjẹ. Inú òun ati gbogbo ìdílé rẹ̀ dùn pupọ nítorí ó ti gba Ọlọrun gbọ́.

35 Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, àwọn adájọ́ rán àwọn iranṣẹ sí ẹni tí ń ṣọ́ ilé ẹ̀wọ̀n pé, kí ó dá àwọn eniyan náà sílẹ̀.

36 Ẹni tí ó ń ṣọ́ ilé ẹ̀wọ̀n náà bá lọ jíṣẹ́ fún Paulu pé, “Àwọn adájọ́ ti ranṣẹ pé kí á da yín sílẹ̀. Ẹ jáde kí ẹ máa lọ ní alaafia.”

37 Ṣugbọn Paulu sọ fún wọn pé, “Wọ́n nà wá ní gbangba láì ká ẹ̀bi mọ́ wa lọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ ọmọ-ìbílẹ̀ Romu ni wá. Wọ́n sọ wá sẹ́wọ̀n, wọ́n wá fẹ́ tì wá jáde níkọ̀kọ̀. Rárá o! Kí àwọn fúnra wọn wá kó wa jáde.”

38 Àwọn iranṣẹ tí àwọn adájọ́ rán wá lọ ròyìn ọ̀rọ̀ wọnyi fún wọn. Ẹ̀rù bà wọ́n nígbà tí wọ́n gbọ́ pé ọmọ-ìbílẹ̀ Romu ni wọ́n jẹ́.

39 Wọ́n bá wá, wọ́n bẹ̀ wọ́n. Wọ́n sìn wọ́n jáde, wọ́n bá rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n kúrò ninu ìlú.

40 Nígbà tí wọ́n jáde kúrò lẹ́wọ̀n, wọ́n lọ sí ilé Lidia. Lẹ́yìn tí wọ́n rí àwọn onigbagbọ, tí wọ́n sì gbà wọ́n níyànjú, wọ́n kúrò níbẹ̀.

Categories
ÌṢE ÀWỌN APOSTELI

ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 17

Ìdàrúdàpọ̀ ní Tẹsalonika

1 Wọ́n kọjá ní Amfipoli ati Apolonia kí wọn tó dé Tẹsalonika. Ilé ìpàdé àwọn Juu kan wà níbẹ̀.

2 Gẹ́gẹ́ bí àṣà Paulu, ó wọ ibẹ̀ tọ̀ wọ́n lọ. Fún ọ̀sẹ̀ mẹta ni ó fi ń bá wọn fi ọ̀rọ̀ wé ọ̀rọ̀ láti inú Ìwé Mímọ́.

3 Ó ń ṣe àlàyé fún wọn, ó tún ń tọ́ka sí àkọsílẹ̀ inú Ìwé Mímọ́ láti fihàn pé dandan ni kí Mesaya jìyà, kí ó jinde kúrò ninu òkú. Lẹ́yìn náà ó sọ fún wọn pé, Mesaya yìí náà ni Jesu tí òun ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ fún wọn.

4 Àwọn kan ninu wọn gbàgbọ́, wọ́n fara mọ́ Paulu ati Sila. Ọ̀pọ̀ ninu wọn jẹ́ Giriki, wọ́n ń sin Ọlọrun; pupọ ninu àwọn obinrin sì jẹ́ eniyan pataki-pataki.

5 Ṣugbọn ara ta àwọn Juu nígbà tí wọ́n rí i pé àwọn eniyan pupọ gba ọ̀rọ̀ Paulu ati Sila. Wọ́n bá lọ mú ninu àwọn tí wọ́n ń fẹsẹ̀ wọ́lẹ̀ kiri, àwọn jàgídíjàgan, wọ́n kó wọn jọ. Wọ́n bá dá ìrúkèrúdò sílẹ̀ ninu ìlú. Wọ́n lọ ṣùrù bo ilé Jasoni, wọ́n ń wá Paulu ati Sila kí wọ́n lè fà wọ́n lọ siwaju àwọn ará ìlú.

6 Nígbà tí wọn kò rí wọn, wọ́n fa Jasoni ati díẹ̀ ninu àwọn onigbagbọ lọ siwaju àwọn aláṣẹ ìlú. Wọ́n ń kígbe pé, “Àwọn tí wọn ń da gbogbo ayé rú nìyí; wọ́n ti dé ìhín náà.

7 Jasoni sì ti gbà wọ́n sílé. Gbogbo wọn ń ṣe ohun tí ó lòdì sí àṣẹ Kesari. Wọ́n ní: ọba mìíràn wà, ìyẹn ni Jesu!”

8 Ọkàn àwọn eniyan ati àwọn aláṣẹ ìlú dààmú nígbà tí wọ́n gbọ́ báyìí.

9 Wọ́n bá gba owó ìdúró lọ́wọ́ Jasoni ati àwọn yòókù, wọ́n bá dá wọn sílẹ̀.

Paulu ati Sila lọ sí Beria

10 Nígbà tí ilẹ̀ ṣú, àwọn onigbagbọ tètè ṣe ètò láti mú Paulu ati Sila lọ sí Beria. Nígbà tí wọ́n dé ibẹ̀, wọ́n lọ sí ilé ìpàdé àwọn Juu.

11 Àwọn yìí ṣe onínú rere ju àwọn Juu ti Tẹsalonika lọ. Wọ́n fi ìtara gbọ́ ọ̀rọ̀ náà. Lojoojumọ ni wọ́n ń wá inú Ìwé Mímọ́ wò láti rí bí àwọn ohun tí wọ́n kọ́ wọn rí bẹ́ẹ̀.

12 Pupọ ninu wọn gbàgbọ́, ati pupọ ninu àwọn Giriki tí wọ́n jẹ́ eniyan pataki-pataki, lọkunrin ati lobinrin.

13 Ṣugbọn nígbà tí àwọn Juu ní Tẹsalonika mọ̀ pé Paulu ti tún waasu ọ̀rọ̀ Ọlọrun ní Beria, wọ́n wá sibẹ láti ṣe màdàrú ati láti dá rúkèrúdò sílẹ̀.

14 Lẹsẹkẹsẹ ni àwọn onigbagbọ bá ṣe ètò fún Paulu láti lọ sí èbúté. Ṣugbọn Sila ati Timoti dúró ní Beria.

15 Àwọn tí ó sin Paulu lọ mú un dé Atẹni. Wọ́n wá gba ìwé pada fún Sila ati Timoti pé kí wọ́n tètè wá bá a.

Paulu ní Atẹni

16 Nígbà tí Paulu ń dúró dè wọ́n ní Atẹni, ó rí ìlú náà bí ó ti kún fún ère oriṣa. Eléyìí sì dùn ún dọ́kàn.

17 Nítorí náà, ó ń bá àwọn Juu ati àwọn olùfọkànsìn tí kì í ṣe Juu jiyàn ninu ilé ìpàdé ní ojoojumọ. Bẹ́ẹ̀ náà ni ó ń ṣe láàrin ọjà, ó ń bá ẹnikẹ́ni tí ó bá wà nítòsí sọ̀rọ̀.

18 Àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n kan ninu àwọn ọmọlẹ́yìn Epikurusi ati àwọn Sitoiki bẹ̀rẹ̀ sí bá a jiyàn. Àwọn kan ń sọ pé, “Kí ni aláhesọ yìí ń wí?”

Àwọn mìíràn ní, “Ó jọ pé òjíṣẹ́ oriṣa àjèjì kan ni!” Nítorí ó ń waasu nípa Jesu ati ajinde.

19 Ni wọ́n bá ní kí ó kálọ sí Òkè Areopagu. Wọ́n wá bi í pé, “Ǹjẹ́ a lè mọ ohun tí ẹ̀kọ́ titun tí ò ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí jẹ́?

20 Nítorí ohun tí ò ń sọ ṣe àjèjì létí wa. A sì fẹ́ mọ ìtumọ̀ rẹ̀.”

21 (Gbogbo àwọn ará Atẹni ní tiwọn, ati àwọn àlejò tí ó ń gbé ibẹ̀, kí wọn ṣá máa ròyìn nǹkan titun tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ wọ̀lú ni iṣẹ́ tiwọn. Bí wọn bá ti gbọ́ èyí, ohun tí ó ń ṣe wọ́n tán.)

22 Paulu bá dìde dúró láàrin ìgbìmọ̀ tí ó wà ní Òkè Areopagu, ó ní, “Ẹ̀yin ará Atẹni, ó hàn lọ́tùn-ún lósì sí ẹni tí ó bá wò ó pé ẹ kò fi ọ̀rọ̀ oriṣa ṣeré.

23 Bí mo ti ń lọ tí mò ń bọ̀ ni mò ń fojú wo àwọn ohun tí ẹ̀ ń sìn. Mo rí pẹpẹ ìrúbọ kan tí ẹ kọ àkọlé báyìí sí ara rẹ̀ pé: ‘Sí Ọlọrun tí ẹnìkan kò mọ̀.’ Ohun tí ẹ kò mọ̀ tí ẹ̀ ń sìn, òun ni mò ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ fun yín.

24 Ọlọrun tí ó dá ayé ati gbogbo nǹkan tí ó wà ninu rẹ̀, Oluwa ọ̀run ati ayé, kì í gbé ilé oriṣa àfọwọ́kọ́;

25 bẹ́ẹ̀ ni kò sí ohun tí kò ní, tí a óo sọ pé kí eniyan fún un, nítorí òun fúnra rẹ̀ ni ó ń fún gbogbo eniyan ní ẹ̀mí, èémí ati ohun gbogbo.

26 Òun ni ó dá gbogbo orílẹ̀-èdè láti inú ẹnìkan ṣoṣo láti máa gbé gbogbo ilẹ̀ ayé. Kí ó tó dá wọn, ó ti ṣe ìpinnu tẹ́lẹ̀ nípa ìgbà tí wọn yóo gbé ní ayé ati ààlà ibi tí wọn yóo máa gbé.

27 Ó dá wọn láti máa wá òun Ọlọrun, bí ó bá ṣeéṣe, kí wọ́n fọwọ́ kàn án, kí wọ́n rí i. Kò sì kúkú jìnnà sí ẹnìkan kan ninu wa.

28 Nítorí ẹnìkan sọ níbìkan pé:

‘Ninu rẹ̀ ni à ń gbé,

tí à ń rìn kiri,

tí a wà láàyè.’

Àwọn kan ninu àwọn akéwì yín pàápàá ti sọ ohun tó jọ bẹ́ẹ̀; wọ́n ní,

‘Ọmọ rẹ̀ ni a jẹ́.’

29 Nígbà tí a jẹ́ ọmọ Ọlọrun, kò yẹ kí á rò pé Ọlọrun dàbí ère wúrà, tabi fadaka, tabi òkúta, ère tí oníṣẹ́ ọnà ṣe pẹlu ọgbọ́n ati èrò eniyan.

30 Ọlọrun ti fojú fo àkókò tí eniyan kò ní ìmọ̀ dá. Ṣugbọn ní àkókò yìí, ó pàṣẹ fún gbogbo eniyan ní ibi gbogbo láti ronupiwada.

31 Nítorí ó ti yan ọjọ́ tí yóo fi òdodo ṣe ìdájọ́ gbogbo ayé nípa ọkunrin tí ó ti yàn. Ó fi òtítọ́ èyí han gbogbo eniyan nígbà tí ó jí ẹni náà dìde kúrò ninu òkú.”

32 Nígbà tí wọ́n gbọ́ pé òkú jinde, àwọn kan ń ṣe yẹ̀yẹ́, àwọn mìíràn ní, “A tún fẹ́ gbọ́ nípa ọ̀rọ̀ yìí nígbà mìíràn.”

33 Paulu bá jáde kúrò láàrin wọn.

34 Àwọn kan ninu wọn bá fara mọ́ ọn, wọ́n sì gbàgbọ́. Ọ̀kan ninu wọn ni Dionisu, adájọ́ ní kóòtù Òkè Areopagu, ati obinrin kan tí ń jẹ́ Damarisi ati àwọn ẹlòmíràn pẹlu wọn.

Categories
ÌṢE ÀWỌN APOSTELI

ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 18

Iṣẹ́ Paulu ní Kọrinti

1 Lẹ́yìn èyí, Paulu kúrò ní Atẹni, ó lọ sí Kọrinti.

2 Ó rí Juu kan níbẹ̀, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Akuila, ará Pọntu. Òun ati Pirisila iyawo rẹ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ ti ilẹ̀ Itali dé ni, nítorí ọba Kilaudiu pàṣẹ pé kí gbogbo àwọn Juu kúrò ní ìlú Romu. Paulu bá lọ sọ́dọ̀ wọn.

3 Nítorí pé iṣẹ́ kan náà ni wọ́n ń ṣe, Paulu lọ wọ̀ lọ́dọ̀ wọn, ó sì ń ṣiṣẹ́. Iṣẹ́ ọnà awọ tí wọ́n fi ń ṣe àgọ́ ni wọ́n ń ṣe.

4 Ní gbogbo Ọjọ́ Ìsinmi, a máa bá àwọn eniyan sọ̀rọ̀; ó fẹ́ yí àwọn Juu ati Giriki lọ́kàn pada.

5 Nígbà tí Sila ati Timoti dé láti Masedonia, Paulu wá fi gbogbo àkókò rẹ̀ sílẹ̀ fún iwaasu, ó ń tẹnu mọ́ ọn fún àwọn Juu pé Jesu ni Mesaya.

6 Ṣugbọn nígbà tí àwọn kan takò ó, tí wọn ń sọ ìsọkúsọ, ó gbọn ẹ̀wù rẹ̀ sí wọn lójú, ó ní, “Ẹ̀jẹ̀ yín wà lọ́rùn yín. Ọwọ́ tèmi mọ́. Láti ìgbà yìí lọ èmi yóo lọ sọ́dọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn.”

7 Ni ó bá kúrò níbẹ̀, ó wọ ilé ẹnìkan tí ó ń jẹ́ Titiu Jusitu, ẹnìkan tí ń sin Ọlọrun. Ilé rẹ̀ fẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹlu ilé ìpàdé àwọn Juu.

8 Kirisipu, ẹni tí ń darí ètò ilé ìpàdé àwọn Juu gba Oluwa gbọ́ pẹlu gbogbo ilé rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni pupọ ninu àwọn ará Kọrinti; nígbà tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ Oluwa, wọ́n gbàgbọ́, wọ́n bá ṣe ìrìbọmi.

9 Ní alẹ́ ọjọ́ kan, Paulu rí ìran kan. Ninu ìran náà Oluwa sọ fún un pé, “Má bẹ̀rù, máa waasu, má dákẹ́.

10 Nítorí n óo wà pẹlu rẹ. Kò sí ẹni tí yóo fọwọ́ kàn ọ́ láti ṣe ọ́ níbi. Nítorí mo ní eniyan pupọ ninu ìlú yìí.”

11 Paulu gbé ààrin wọn fún ọdún kan ati oṣù mẹfa, ó ń kọ́ wọn ní ọ̀rọ̀ Ọlọrun.

12 Ṣugbọn nígbà tí Galio di gomina Akaya, àwọn Juu fi ohùn ṣọ̀kan láti dìde sí Paulu. Wọ́n bá mú un lọ sí kóòtù níwájú Galio.

13 Wọ́n ní, “Ọkunrin yìí ń kọ́ àwọn eniyan láti sin Ọlọrun ní ọ̀nà tí ó lòdì sí òfin.”

14 Bí Paulu ti fẹ́ lanu láti fèsì, Galio sọ fún àwọn Juu pé, “Ẹ̀yin Juu, bí ó bá jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ kan tabi ọ̀ràn burúkú kan ni ẹ mú wá, ǹ bá gbọ́ ohun tí ẹ ní sọ;

15 ṣugbọn tí ó bá jẹ́ àríyànjiyàn nípa àwọn ọ̀rọ̀ tabi orúkọ, tabi òfin yín, ẹ lọ rí sí i fúnra yín. N kò fẹ́ dá irú ẹjọ́ bẹ́ẹ̀.”

16 Ni ó bá lé wọn kúrò ní kóòtù.

17 Ni gbogbo wọ́n bá mú Sositene, olórí ilé ìpàdé àwọn Juu, wọ́n ń lù ú níwájú kóòtù. Ṣugbọn Galio kò pé òun rí wọn.

Paulu Pada Lọ sí Antioku

18 Paulu tún dúró fún ìgbà díẹ̀ sí i. Lẹ́yìn náà ó dágbére fún àwọn onigbagbọ, ó bá wọ ọkọ̀ ojú omi lọ sí Siria; Pirisila ati Akuila bá a lọ. Paulu gé irun rẹ̀ ní ìlú Kẹnkiria nítorí pé ó ti jẹ́ ẹ̀jẹ́ kan.

19 Nígbà tí wọ́n dé Efesu, Paulu fi Pirisila ati Akuila sílẹ̀, ó lọ sinu ilé ìpàdé àwọn Juu, ó lọ bá àwọn Juu sọ̀rọ̀.

20 Wọ́n bẹ̀ ẹ́ kí ó dúró lọ́dọ̀ wọn fún àkókò díẹ̀ sí i, ṣugbọn kò gbà.

21 Bí ó ti fẹ́ kúrò lọ́dọ̀ wọn, ó ní, “N óo tún pada wá sí ọ̀dọ̀ yín bí Ọlọrun bá fẹ́.” Ó bá kúrò ní Efesu.

22 Nígbà tí ó gúnlẹ̀ ní Kesaria, ó lọ kí ìjọ ní Jerusalẹmu. Lẹ́yìn náà ó lọ sí Antioku.

23 Ó dúró níbẹ̀ fún ìgbà díẹ̀. Ó bá tún kúrò, ó la agbègbè Galatia ati ti Firigia já, ó ń mú gbogbo àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu lọ́kàn le.

Apolo Dé Efesu

24 Ọkunrin Juu kan, ará Alẹkisandria, dé sí Efesu. Orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Apolo. Ọ̀rọ̀ dùn lẹ́nu rẹ̀, ó sì mọ Ìwé Mímọ́ pupọ.

25 A ti fi ọ̀nà Oluwa kọ́ ọ, a máa sọ̀rọ̀ pẹlu ìtara; a sì máa kọ́ àwọn eniyan lẹ́kọ̀ọ́ nípa Jesu ní àkọ́yé. Ṣugbọn ìrìbọmi tí Johanu ṣe nìkan ni ó mọ̀.

26 Ó bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ pẹlu ìgboyà ninu ilé ìpàdé àwọn Juu. Nígbà tí Pirisila ati Akuila gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, wọ́n mú un, wọ́n túbọ̀ fi ọ̀nà Ọlọrun yé e yékéyéké.

27 Nígbà tí ó fẹ́ kọjá lọ sí Akaya, àwọn onigbagbọ ní Efesu fún un ní ìwúrí, wọ́n kọ ìwé sí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu ní Akaya pé kí wọ́n gbà á tọwọ́-tẹsẹ̀. Nígbà tí Apolo dé Akaya, ó wúlò lọpọlọpọ fún àwọn tí wọ́n gbàgbọ́ nípa oore-ọ̀fẹ́ níbẹ̀.

28 Bí ó bá bá àwọn Juu jiyàn níwájú gbogbo àwùjọ, a máa borí wọn, kedere ni ó ń fihàn láti inú Ìwé Mímọ́ pé Jesu ni Mesaya.

Categories
ÌṢE ÀWỌN APOSTELI

ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 19

Paulu Dé Efesu

1 Nígbà tí Apolo wà ní Kọrinti, Paulu gba ọ̀nà ilẹ̀ la àwọn ìlú tí ó wà ní àríwá Antioku kọjá títí ó fi dé Efesu. Ó rí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu mélòó kan níbẹ̀.

2 Ó bi wọ́n pé, “Ǹjẹ́ ẹ gba Ẹ̀mí Mímọ́ nígbà tí ẹ gba Jesu gbọ́?”

Wọ́n dá a lóhùn pé, “Rárá o! A kò tilẹ̀ gbọ́ ọ rí pé nǹkankan wà tí ń jẹ́ Ẹ̀mí Mímọ́.”

3 Paulu tún bi wọ́n pé, “Ìrìbọmi ti ta ni ẹ ṣe?”

Wọ́n ní, “Ìrìbọmi ti Johanu ni.”

4 Paulu bá sọ pé, “Ìrìbọmi pé a ronupiwada ni Johanu ṣe. Ó ń sọ fún àwọn eniyan pé kí wọ́n gba ẹni tí ó ń bọ̀ lẹ́yìn òun gbọ́. Ẹni náà ni Jesu.”

5 Nígbà tí wọ́n gbọ́, wọ́n gbà fún Paulu, ó sì rì wọ́n bọmi lórúkọ Oluwa Jesu.

6 Nígbà tí Paulu gbé ọwọ́ lé wọn, Ẹ̀mí Mímọ́ bà lé wọn, wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí fi èdè mìíràn sọ̀rọ̀, wọ́n ń sọ àsọtẹ́lẹ̀.

7 Gbogbo àwọn ọkunrin náà tó mejila.

8 Paulu wọ inú ilé ìpàdé lọ. Fún oṣù mẹta ni ó fi ń sọ̀rọ̀ pẹlu ìgboyà; ó ń fi ọ̀rọ̀ yé àwọn eniyan nípa ìjọba Ọlọrun, ó ń gbìyànjú láti yí wọn lọ́kàn pada.

9 Ṣugbọn nígbà tí àwọn kan ṣe agídí, tí wọn kò gba ọ̀rọ̀ rẹ̀ gbọ́, tí wọn ń sọ̀rọ̀ burúkú sí ọ̀nà Oluwa níwájú gbogbo àwùjọ, Paulu yẹra kúrò lọ́dọ̀ wọn, ó kó àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu lọ sí gbọ̀ngàn Tirani, ó sì ń bá wọn sọ̀rọ̀ níbẹ̀ lojoojumọ.

10 Báyìí ló ṣe fún ọdún meji, tí ó fi jẹ́ pé gbogbo àwọn tí ń gbé Esia: ati Juu ati Giriki, ni ó gbọ́ ọ̀rọ̀ Oluwa.

Àwọn Ọmọ Sikefa

11 Ọlọrun fún Paulu lágbára láti ṣe iṣẹ́ ìyanu tóbẹ́ẹ̀

12 tí àwọn eniyan fi ń mú ìdikù tabi aṣọ-iṣẹ́ tí ó ti kan ara Paulu, lọ fi lé àwọn aláìsàn lára, àìsàn wọn sì ń fi wọ́n sílẹ̀, ẹ̀mí burúkú sì ń jáde kúrò lára wọn.

13 Àwọn Juu kan tí wọ́n ti ń kiri láti ìlú dé ìlú, tí wọn ń lé ẹ̀mí burúkú jáde kúrò ninu àwọn eniyan, fẹ́ máa ṣe bíi Paulu nípa pípe orúkọ Oluwa Jesu lé àwọn tí ó ní ẹ̀mí burúkú lórí. Wọ́n á máa wí pé, “Mo pàṣẹ fun yín lórúkọ Jesu tí Paulu ń ròyìn nípa rẹ̀.”

14 Àwọn Juu meje kan tí wọn jẹ́ ọmọ Sikefa Olórí Alufaa wà, tí wọn ń ṣe bẹ́ẹ̀.

15 Ẹni tí ẹ̀mí burúkú wà ninu rẹ̀ bá bi wọ́n pé, “Mo mọ Jesu; mo sì mọ Paulu. Tiyín ti jẹ́?”

16 Ni ọkunrin tí ẹ̀mí burúkú wà ninu rẹ̀ bá fò mọ́ wọn; ó gbé ìjà ńlá kò wọ́n, ó sì ṣẹgun gbogbo wọn, ó ṣe wọ́n léṣe tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi sá jáde ninu ilé náà ní ìhòòhò, tàwọn ti ọgbẹ́ lára.

17 Gbogbo àwọn Juu ati àwọn Giriki tí ó ń gbé Efesu ni wọ́n gbọ́ nípa ọ̀rọ̀ yìí. Ẹ̀rù ba gbogbo wọn; wọ́n sì gbé orúkọ Jesu Oluwa ga.

18 Pupọ ninu àwọn onigbagbọ ni wọ́n jẹ́wọ́ ohun tí wọ́n ti ṣe, tí wọ́n tún tú àṣírí idán tí wọn ń pa.

19 Àwọn mélòó kan ninu àwọn oníṣẹ́ òkùnkùn kó ìwé idán wọn jọ, wọ́n bá dáná sun wọ́n lójú gbogbo eniyan. Nígbà tí wọ́n ṣírò iye owó àwọn ìwé ọ̀hún, wọ́n rí i pé ó tó ọ̀kẹ́ meji ààbọ̀ (50,000) owó fadaka.

20 Báyìí ni ọ̀rọ̀ Oluwa fi agbára hàn; ó ń tàn kálẹ̀, ó sì ń lágbára.

Ìrúkèrúdò Bẹ́ sílẹ̀ ní Efesu

21 Lẹ́yìn gbogbo nǹkan wọnyi, Paulu pinnu lọ́kàn rẹ̀ láti gba Masedonia lọ sí Akaya, kí ó wá ti ibẹ̀ lọ sí Jerusalẹmu. Ó ní, “Nígbà tí mo bá dé ibẹ̀, ó yẹ kí n fojú ba Romu náà.”

22 Ó bá rán àwọn meji ninu àwọn olùrànlọ́wọ́ rẹ̀, Timoti ati Erastu, lọ sí Masedonia ṣugbọn òun alára dúró fún ìgbà díẹ̀ sí i ní Esia.

23 Ní àkókò náà, rògbòdìyàn bẹ́ sílẹ̀, tí kì í ṣe kékeré, nípa ọ̀nà Oluwa.

24 Ọkunrin kan wà tí ń jẹ́ Demeteriu, alágbẹ̀dẹ fadaka. A máa fi fadaka ṣe ilé ìsìn ti oriṣa Atẹmisi; èyí a sì máa mú èrè pupọ wá fún àwọn tí ń ṣe iṣẹ́ ọnà yìí.

25 Demeteriu wá pe àpèjọ àwọn alágbẹ̀dẹ fadaka ati àwọn tí iṣẹ́ wọn fara jọra. Ó ní, “Ẹ̀yin eniyan wa, ẹ mọ̀ pé ninu iṣẹ́ yìí ni a ti ń rí èrè wa.

26 Ẹ wá rí i, ẹ tún ti gbọ́ pé kì í ṣe ní Efesu nìkan ni, ṣugbọn ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ pé ní gbogbo Esia ni Paulu yìí ti ń yí ọ̀pọ̀ eniyan lọ́kàn pada. Ó ní àwọn ohun tí a fọwọ́ ṣe kì í ṣe oriṣa!

27 Ewu wà fún wa pé, iṣẹ́ wa yóo di ohun tí eniyan kò ní kà sí mọ́. Ṣugbọn èyí nìkan kọ́, ewu tí ó tún wà ni pé, ilé ìsìn oriṣa ńlá wa, Atẹmisi, yóo di ohun tí ẹnikẹ́ni kò ní ṣújá mọ́. Láìpẹ́ kò sí ẹni tí yóo gbà pé oriṣa wa tóbi mọ́, oriṣa tí gbogbo Esia ati gbogbo àgbáyé ń sìn!”

28 Nígbà tí wọ́n gbọ́, inú bí wọn pupọ. Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí kígbe, wọ́n ń wí pé, “Oriṣa ńlá ni Atẹmisi, oriṣa àwọn ará Efesu!”

29 Ni gbogbo ìlú bá dàrú. Wọ́n mú Gaiyu ati Arisitakọsi ará Masedonia, àwọn ẹlẹgbẹ́ Paulu ninu ìrìn àjò rẹ̀, gbogbo wọn bá rọ́ lọ sí ilé-ìṣeré.

30 Paulu fẹ́ wọ ibẹ̀ lọ bá àwọn èrò ṣugbọn àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu kò gbà fún un.

31 Àwọn ọ̀rẹ́ Paulu kan tí wọ́n jẹ́ ìjòyè ní agbègbè Esia ranṣẹ lọ bẹ̀ ẹ́ pé kí ó má yọjú sí ilé-ìṣeré nítorí gbogbo àwùjọ ti dàrú.

32 Bí àwọn kan ti ń kígbe bákan, bẹ́ẹ̀ ni àwọn mìíràn ń kígbe bá mìíràn. Ọpọlọpọ kò tilẹ̀ mọ ìdí rẹ̀ tí wọ́n fi péjọ!

33 Àwọn mìíràn rò pé Alẹkisanderu ni ó dá gbogbo rẹ̀ sílẹ̀, nítorí òun ni àwọn Juu tì siwaju. Alẹkisanderu fúnra rẹ̀ gbọ́wọ́ sókè, ó fẹ́ bá àwọn èrò sọ̀rọ̀.

34 Nígbà tí wọ́n mọ̀ pé Juu ni, wọ́n figbe ta, wọ́n ń pariwo fún ìwọ̀n wakati meji. Wọ́n ń kígbe pé, “Oriṣa ńlá ni Atẹmisi, oriṣa àwọn ará Efesu!”

35 Akọ̀wé ìgbìmọ̀ ìlú ló mú kí wọ́n dákẹ́. Ó wá sọ pé, “Ẹ̀yin ará Efesu, ta ni kò mọ̀ pé ìlú Efesu ni ó ń tọ́jú ilé ìsìn Atẹmisi oriṣa ńlá, ati òkúta rẹ̀ tí ó bọ́ sílẹ̀ láti ọ̀run?

36 Kò sí ẹni tí ó lè wí pé kì í ṣe bẹ́ẹ̀. Ó yẹ kí ẹ fara balẹ̀ nígbà náà; kí a má fi ìwàǹwára ṣe ohunkohun.

37 Nítorí àwọn ọkunrin tí ẹ mú wá yìí, kò ja ilé oriṣa lólè, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sọ ìsọkúsọ sí oriṣa wa.

38 Bí Demeteriu ati àwọn oníṣẹ́ ọnà tí ó wà pẹlu rẹ̀ bá ní ẹ̀sùn kan sí ẹnikẹ́ni, kóòtù wà; àwọn gomina sì ń bẹ. Ẹ jẹ́ kí wọ́n lọ pe ara wọn lẹ́jọ́ níbẹ̀.

39 Bí ẹ bá tún ní ọ̀rọ̀ mìíràn tí ó jù yìí lọ, a óo máa yanjú rẹ̀ ní ìgbà tí a bá ń ṣe ìpàdé.

40 Nítorí bí a ò bá ṣọ́ra, a óo dé ilé ẹjọ́ fún ìrúkèrúdò ọjọ́ òní, kò sì sí ohun tí a lè sọ pé ó fà á bí wọ́n bá bi wá.”

41 Lẹ́yìn tí ó ti sọ báyìí tán, ó tú àwọn eniyan náà ká.