Categories
ÌṢE ÀWỌN APOSTELI

ÌṢE ÀWỌN APOSTELI Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Àfikún ati ìgbésẹ̀ siwaju àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kọ sinu

Ìyìn Rere Luku

ni

Ìṣe Àwọn Aposteli

jẹ́. Kókó ète ìwé náà ni láti sọ bí Ẹ̀mí Mímọ́ ṣe darí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu láti tan Ìròyìn Ayọ̀ náà káàkiri ní Jerusalẹmu ati ní Judia, títí dé òpin ayé (1:8). Ìtàn ìdìde ati ìdàgbàsókè igbagbọ ni, bí ó ṣe bẹ̀rẹ̀ láàrin àwọn Juu títí ó fi di igbagbọ gbogbo àgbáyé. Ọ̀kan ninu àwọn ohun tí ó jẹ ẹni tí ó kọ ìwé yìí lógún ni láti mú kí ó dá àwọn òǹkàwé rẹ̀ lójú pé àwọn onigbagbọ kì í ṣe òṣèlú onírúkèrúdò tí yóo dojú ìjọba Romu délẹ̀, àtipé igbagbọ ni ìmúṣẹ ìsìn àwọn Juu.

A lè pín ìwé

Ìṣe Àwọn Aposteli

sí ọ̀nà mẹta tí ó ń fi hàn bí àwọn ibi tí a ti ń waasu Ìròyìn Ayọ̀ nípa Jesu ti ń gbòòrò sí i, ati bí a ti ṣe fi ìdí ìjọ Ọlọrun múlẹ̀: (1) Ìbẹ̀rẹ̀ ìdàgbàsókè ati ìtànkálẹ̀ igbagbọ ní Jerusalẹmu lẹ́yìn ìgòkè-re-ọ̀run Jesu; (2) bí igbagbọ ṣe tàn káàkiri àwọn agbègbè mìíràn ní Palẹstini (3) ati bí ó ṣe tún tàn káàkiri àwọn agbègbè tí ó yí òkun Mẹditarenia ká, títí ó fi dé Romu.

Nǹkankan pataki tíí máa ń jẹ jáde lemọ́lemọ́ ninu

Ìṣe Àwọn Aposteli

ni iṣẹ́ Ẹ̀mí Mímọ́, tí ó fi tagbára-tagbára sọ̀kalẹ̀, tí ó sì bà lé àwọn onigbagbọ lórí ní Jerusalẹmu ní ọjọ́ Pẹntikọsti. Ẹ̀mí Mímọ́ yìí ní ń darí ìjọ ati àwọn adarí ìjọ, tí ó sì ń fún wọn ní agbára ninu gbogbo àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí a sọ nípa rẹ̀ ninu ìwé yìí. A ṣe àkójọ iṣẹ́ tí àwọn onigbagbọ àkọ́kọ́ níláti jẹ́ ní ṣókí ninu àwọn iwaasu bíi mélòó kan. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kọ sinu ìwé Ìṣe Àwọn Aposteli fi agbára iṣẹ́ tí wọn ń jẹ́ yìí hàn ninu ìgbé-ayé àwọn onigbagbọ ati ìrẹ́pọ̀ àwọn ọmọ ìjọ.

Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí

Ìpalẹ̀mọ́ fún ìjẹ́rìí 1:1-26

a. Àṣẹ ìkẹyìn tí Jesu pa ati ìlérí tí ó ṣe 1:1-14

b. Ẹni tí ó gba ipò Judasi 1:15-26

Ìjẹ́rìí ní Jerusalẹmu 2:1–8:3

Ìjẹ́rìí ní Judia ati ní Samaria 8:4–12:25

Iṣẹ́ Paulu 13:1–28:31

a. Ìrìn àjò ìjíyìn rere kinni 13:1–14:28

b. Àjọ tí wọ́n ṣe ní Jerusalẹmu 15:1-35

d. Ìrìn àjò ìjíyìn rere keji 15:36–18:22

e. Ìrìn àjò ìjíyìn rere kẹta 18:23–21:16

ẹ. Paulu ṣe ẹ̀wọ̀n ní Jerusalẹmu, Kesaria ati Romu 21:17–28:31

Categories
ÌṢE ÀWỌN APOSTELI

ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 1

Jesu Ṣe Ìlérí Ẹ̀mí Mímọ́

1 Tiofilu mi ọ̀wọ́n: Ninu ìwé mi àkọ́kọ́, mo ti sọ nípa gbogbo ohun tí Jesu ṣe ati ẹ̀kọ́ tí ó ń kọ́ àwọn eniyan,

2 títí di ọjọ́ tí a gbé e lọ sókè ọ̀run lẹ́yìn tí ó ti pàṣẹ ohun tí ó fẹ́, nípa Ẹ̀mí Mímọ́, fún àwọn aposteli tí ó ti yàn.

3 Àwọn aposteli yìí ni ó fi ara rẹ̀ hàn láàyè lẹ́yìn ìjìyà rẹ̀ pẹlu ẹ̀rí tí ó dájú. Wọ́n rí i níwọ̀n ogoji ọjọ́, ó sì ń bá wọn sọ̀rọ̀ nípa nǹkan tí ó jẹ mọ́ ti ìjọba Ọlọrun.

4 Nígbà tí ó wà lọ́dọ̀ wọn, ó pàṣẹ fún wọn pé kí wọn má kúrò ní Jerusalẹmu. Ó ní, “Ẹ dúró títí ìlérí tí Baba mí ṣe yóo fi ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti gbọ́ tí mo sọ fun yín.

5 Nítorí omi ni Johanu fi ń ṣe ìwẹ̀mọ́, ṣugbọn Ẹ̀mí Mímọ́ ni a óo fi ṣe ìwẹ̀mọ́ fun yín láìpẹ́ jọjọ.”

Jesu Gòkè Lọ sí Ọ̀run

6 Ní ọjọ́ kan tí gbogbo wọn péjọ, wọ́n bi í pé, “Oluwa, ṣé àkókò tó nisinsinyii tí ìwọ yóo gba ìjọba pada fún Israẹli?”

7 Ó dá wọn lóhùn pé, “Kì í ṣe tiyín láti mọ àkókò tabi ìgbà tí Baba ti fi sí ìkáwọ́ ara rẹ̀ nìkan ṣoṣo.

8 Ṣugbọn ẹ̀yin yóo gba agbára nígbà tí Ẹ̀mí Mímọ́ bá bà lé yin. Ẹ óo wá máa ṣe ẹlẹ́rìí mi ní Jerusalẹmu, ati ní gbogbo Judia ati ní Samaria ati títí dé òpin ilẹ̀ ayé.”

9 Nígbà tí ó ti sọ báyìí tán, bí wọ́n ti ń wò ó, a gbé e sókè, ìkùukùu bò ó, wọn kò sì rí i mọ́.

10 Bí wọ́n ti tẹjú mọ́ òkè bí ó ti ń lọ, àwọn ọkunrin meji tí wọ́n wọ aṣọ funfun dúró tì wọ́n.

11 Wọ́n ní, “Ẹ̀yin ará Galili, kí ló dé tí ẹ fi dúró tí ẹ̀ ń wòkè bẹ́ẹ̀? Jesu kan náà, tí a mú kúrò lọ́dọ̀ yín, lọ sí ọ̀run yìí, yóo tún pada wá bí ẹ ṣe rí i tí ó ń lọ sí ọ̀run.”

A Yan Ẹlòmíràn Dípò Judasi

12 Wọ́n pada sí Jerusalẹmu láti orí òkè tí à ń pè ní Òkè Olifi. Òkè náà súnmọ́ Jerusalẹmu, kò tó ibùsọ̀ kan sí ìlú.

13 Nígbà tí wọ́n wọ inú ilé, wọ́n lọ sí iyàrá òkè níbi tí wọn ń gbé. Àwọn tí wọ́n jọ ń gbé ni Peteru, Johanu, Jakọbu, Anderu, Filipi, Tomasi, Batolomiu, Matiu, Jakọbu ọmọ Alfeu, Simoni ti ẹgbẹ́ Seloti ati Judasi ọmọ Jakọbu.

14 Gbogbo wọn ń fi ọkàn kan gbadura nígbà gbogbo pẹlu àwọn obinrin ati Maria ìyá Jesu ati àwọn arakunrin Jesu.

15 Ní ọjọ́ kan, Peteru dìde láàrin àwọn arakunrin tí wọ́n tó ọgọfa eniyan, ó ní,

16 “Ẹ̀yin ará, dandan ni pé kí ohun tí Ẹ̀mí Mímọ́ sọ ninu Ìwé Mímọ́ láti ẹnu Dafidi ṣẹ, nípa ọ̀rọ̀ Judasi tí ó ṣe amọ̀nà àwọn tí ó mú Jesu.

17 Nítorí ọ̀kan ninu wa ni, ó sì ní ìpín ninu iṣẹ́ yìí.”

18 (Ó ra ilẹ̀ kan pẹlu owó tí ó gbà fún ìwà burúkú rẹ̀, ni ó bá ṣubú lulẹ̀, ikùn rẹ̀ sì bẹ́, gbogbo ìfun rẹ̀ bá tú jáde.

19 Gbogbo àwọn eniyan tí ó ń gbé Jerusalẹmu ni ó mọ̀ nípa èyí. Wọ́n bá ń pe ilẹ̀ náà ní “Akelidama” ní èdè wọn. Ìtumọ̀ èyí ni “Ilẹ̀ Ẹ̀jẹ̀.”)

20 “Ọ̀rọ̀ náà rí bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀ ninu Ìwé Orin Dafidi pé,

‘Kí ibùgbé rẹ̀ di ahoro,

kí ẹnikẹ́ni má gbé ibẹ̀.’

Ati pé,

‘Kí á fi ipò rẹ̀ fún ẹlòmíràn.’

21-22 “Nítorí náà, ẹ̀tọ́ ni kí á yan ẹnìkan ninu àwọn tí ó ti wà pẹlu wa ní gbogbo àkókò tí Jesu Oluwa ti ń wọlé, tí ó ń jáde pẹlu wa, láti àkókò tí Johanu ti ń ṣe ìrìbọmi títí di ọjọ́ tí a fi mú Jesu kúrò lọ́dọ̀ wa, kí olúwarẹ̀ lè jẹ́ ẹlẹ́rìí ajinde Jesu, kí ó sì di ọ̀kan ninu wa.”

23 Wọ́n bá gbé ẹni meji siwaju: Josẹfu tí à ń pè ní Basaba, tí ó tún ń jẹ́ Jusitu, ati Matiasi.

24 Wọ́n gbadura pé, “Ìwọ Oluwa, Olùmọ̀ràn gbogbo eniyan, fi ẹni tí o bá yàn ninu àwọn mejeeji yìí hàn,

25 kí ó lè gba iṣẹ́ yìí ati ipò aposteli tí Judasi fi sílẹ̀ láti lọ sí ààyè tirẹ̀.”

26 Wọ́n bá ṣẹ́ gègé. Gègé bá mú Matiasi. Ó bá di ọ̀kan ninu àwọn aposteli mọkanla.

Categories
ÌṢE ÀWỌN APOSTELI

ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 2

Bí Ẹ̀mí Mímọ́ Ti Ṣe Dé

1 Ní ọjọ́ Pẹntikọsti, gbogbo wọn wà pọ̀ ní ibìkan náà.

2 Lójijì ìró kan dún láti ọ̀run, ó dàbí ìgbà tí afẹ́fẹ́ líle bá ń fẹ́, ó sì kún gbogbo inú ilé níbi tí wọ́n gbé jókòó.

3 Wọ́n rí nǹkankan tí ó dàbí ahọ́n iná, tí ó pín ara rẹ̀, tí ó sì bà lé ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn.

4 Gbogbo wọn bá kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí sọ oríṣìíríṣìí èdè mìíràn gẹ́gẹ́ bí Ẹ̀mí ti fi fún wọn láti máa sọ.

5 Ní àkókò náà, àwọn Juu tí wọ́n jẹ́ olùfọkànsìn ti gbogbo orílẹ̀-èdè ayé wá, wọ́n wà ní Jerusalẹmu.

6 Nígbà tí wọ́n gbọ́ ìró yìí, àwọn eniyan rọ́ wá. Ẹnu yà wọ́n nítorí ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn gbọ́ tí wọn ń sọ èdè tirẹ̀.

7 Èyí dà wọ́n láàmú, ó sì yà wọ́n lẹ́nu. Wọ́n ní, “Ṣebí ará Galili ni gbogbo àwọn tí ó ń sọ̀rọ̀ wọnyi?

8 Kí ló dé tí ẹnìkọ̀ọ̀kan wa fi gbọ́ tí wọn ń sọ èdè abínibí rẹ̀?

9 Ati ará Patia, ati ará Media ati ará Elamu; àwọn tí ó ń gbé ilẹ̀ Mesopotamia, ilẹ̀ Judia ati ilẹ̀ Kapadokia; ilẹ̀ Pọntu, ilẹ̀ Esia,

10 ilẹ̀ Firigia ati ilẹ̀ Pamfilia; ilẹ̀ Ijipti ati agbègbè Libia lẹ́bàá Kirene; àwọn àlejò láti ìlú Romu,

11 àwọn Juu ati àwọn aláwọ̀ṣe ẹ̀sìn Juu; àwọn ará Kirete ati àwọn ará Arabia, gbogbo wa ni a gbọ́ tí wọ́n ń sọ àwọn iṣẹ́ ńlá Ọlọrun ní oríṣìíríṣìí èdè wa.”

12 Ìdààmú bá gbogbo àwọn eniyan, ó pá wọn láyà. Wọ́n ń bi ara wọn pé, “Kí ni ìtumọ̀ èyí?”

13 Ṣugbọn àwọn mìíràn ń ṣe ẹlẹ́yà; wọ́n ní, “Wọ́n ti mu ọtí yó ni!”

Iwaasu Peteru ní Ọjọ́ Pẹntikọsti

14 Peteru wá dìde dúró pẹlu àwọn aposteli mọkanla, ó sọ̀rọ̀ sókè, ó ní, “Ẹ̀yin ará, ẹ̀yin Juu, ati gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé Jerusalẹmu, ẹ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yìí ye yín, kí ẹ fetí sí ọ̀rọ̀ mi.

15 Àwọn yìí kò mutí yó bí ẹ ti rò, nítorí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ di agogo mẹsan-an òwúrọ̀ ni.

16 Ṣugbọn ohun tí Joẹli, wolii Ọlọrun ti sọ wá ṣẹ lónìí, tí ó wí pé,

17 ‘Ọlọrun sọ pé,

“Nígbà tí ó bá di àkókò ìkẹyìn,

n óo tú Ẹ̀mí mi jáde sórí gbogbo eniyan.

Àwọn ọmọ yín lọkunrin ati lobinrin yóo sọ àsọtẹ́lẹ̀

àwọn ọdọmọkunrin yín yóo rí ìran,

àwọn àgbà yín yóo sì lá àlá.

18 Àní, ní àkókò náà, n óo tú Ẹ̀mí mi

sórí àwọn ẹrukunrin mi

ati sí orí àwọn ẹrubinrin mi,

àwọn náà yóo sì máa sọ àsọtẹ́lẹ̀.

19 N óo fi ohun ìyanu hàn lókè ọ̀run,

ati ohun abàmì lórí ilẹ̀ ayé;

ẹ̀jẹ̀, ati iná, ìkùukùu ati èéfín.

20 Oòrùn yóo ṣókùnkùn, òṣùpá yóo di ẹ̀jẹ̀,

kí ó tó di ọjọ́ ńlá tí ó lókìkí, ọjọ́ Oluwa.

21 Ní ọjọ́ náà gbogbo ẹni tí ó

bá ké pe orúkọ Oluwa ni a óo gbà là.” ’

22 “Ẹ̀yin ará, ọmọ Israẹli, ẹ fetí sí ọ̀rọ̀ mi. Jesu ará Nasarẹti ni ẹni tí Ọlọrun ti fihàn fun yín pẹlu iṣẹ́ agbára, iṣẹ́ ìyanu, iṣẹ́ abàmì tí Ọlọrun ti ọwọ́ rẹ̀ ṣe láàrin yín. Ẹ̀yin fúnra yín sì mọ̀ bẹ́ẹ̀.

23 Gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Ọlọrun ati ètò tí Ọlọrun ti ṣe tẹ́lẹ̀, a fi í le yín lọ́wọ́, ẹ jẹ́ kí àwọn aláìbìkítà fún Òfin kàn án mọ́ agbelebu, ẹ sì pa á.

24 Ṣugbọn Ọlọrun tú ìdè ikú, ó jí i dìde ninu òkú! Kò jẹ́ kí ikú ní agbára lórí rẹ̀.

25 Nítorí Dafidi sọ nípa rẹ̀ pé,

‘Mo rí Oluwa níwájú mi nígbà gbogbo,

ó wà ní ọwọ́ ọ̀tún mi

nítorí náà ohunkohun kò lè dà mí láàmú.

26 Nítorí náà inú mi dùn, mo bú sẹ́rìn-ín.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé eniyan ẹlẹ́ran-ara ni mí,

sibẹ n óo gbé ìgbé-ayé mi pẹlu ìrètí;

27 nítorí o kò ní fi ọkàn mi sílẹ̀ ní ibùgbé àwọn òkú;

bẹ́ẹ̀ ni o kò ní jẹ́ kí ẹni mímọ́ rẹ rí ìdíbàjẹ́.

28 O ti fi ọ̀nà ìyè hàn mí,

O óo sì fi ayọ̀ kún ọkàn mi níwájú rẹ.’

29 “Ẹ̀yin ará, mo sọ fun yín láìṣe àní-àní pé Dafidi baba-ńlá wa kú, a sì sin ín; ibojì rẹ̀ wà níhìn-ín títí di òní.

30 Ṣugbọn nítorí ó jẹ́ aríran, ó sì mọ̀ pé Ọlọrun ti búra fún òun pé ọ̀kan ninu ọmọ tí òun óo bí ni yóo jókòó lórí ìtẹ́ òun,

31 ó ti rí i tẹ́lẹ̀ pé Mesaya yóo jí dìde kúrò ninu òkú. Ìdí nìyí tí ó fi sọ pé,

‘A kò fi í sílẹ̀ ní ibùgbé àwọn òkú;

bẹ́ẹ̀ ni ẹran-ara rẹ̀ kò díbàjẹ́.’

32 Jesu yìí ni Ọlọrun jí dìde. Gbogbo àwa yìí sì ni ẹlẹ́rìí.

33 Nisinsinyii tí a ti gbé e ka ọwọ́ ọ̀tún Ọlọrun, ó ti gba ìlérí Ẹ̀mí Mímọ́ láti ọ̀dọ̀ Baba, ó wá tú u jáde. Ohun tí ẹ̀ ń rí, tí ẹ sì ń gbọ́ nìyí.

34 Nítorí Dafidi kò gòkè lọ sí ọ̀run. Ohun tí Dafidi sọ ni pé,

‘Oluwa wí fún oluwa mi pé:

Jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi

35 títí n óo fi sọ àwọn ọ̀tá rẹ di tìmùtìmù ìtìsẹ̀ rẹ.’

36 “Nítorí náà kí gbogbo ilé Israẹli mọ̀ dájú pé Jesu yìí tí ẹ̀yin kàn mọ́ agbelebu ni Ọlọrun ti fi ṣe Oluwa ati Mesaya!”

37 Nígbà tí àwọn eniyan gbọ́, ọ̀rọ̀ náà gún wọn lọ́kàn. Wọ́n wá bi Peteru ati àwọn aposteli yòókù pé, “Ẹ̀yin ará, kí ni kí á wá ṣe?”

38 Peteru dá wọn lóhùn pé, “Ẹ ronupiwada, kí á ṣe ìrìbọmi fún ẹnìkọ̀ọ̀kan yín ní orúkọ Kristi. A óo sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín, ẹ óo wá gba ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́.

39 Nítorí ẹ̀yin ni a ṣe ìlérí yìí fún, ati àwọn ọmọ yín ati gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní ọ̀nà jíjìn; a ṣe é fún gbogbo ẹni tí Oluwa Ọlọrun wa bá pè.”

40 Ó tún bá wọn sọ̀rọ̀ pupọ, ó ń rọ̀ wọ́n gidigidi, pé, “Ẹ gba ara yín kúrò ninu ìyà tí ìran burúkú yìí yóo jẹ.”

41 A ṣe ìrìbọmi fún àwọn tí wọ́n gba ọ̀rọ̀ náà. Ní ọjọ́ náà àwọn ẹgbẹẹdogun (3,000) eniyan ni a kà kún ọmọ ìjọ.

42 Wọ́n ń fi tọkàntọkàn kọ́ ẹ̀kọ́ tí àwọn aposteli ń kọ́ wọn; wọ́n wà ní ìrẹ́pọ̀, wọ́n jọ ń jẹun; wọ́n jọ ń gbadura.

Ìgbé-Ayé láàrin Àwọn Onigbagbọ

43 Ẹ̀rù àwọn onigbagbọ wá ń ba gbogbo eniyan. Ọpọlọpọ ni iṣẹ́ ìyanu ati iṣẹ́ abàmì tí a ti ọwọ́ àwọn aposteli ṣe.

44 Gbogbo àwọn onigbagbọ wà ní ibìkan náà. Wọ́n jọ ní ohun gbogbo ní àpapọ̀.

45 Wọ́n ta gbogbo ohun tí wọ́n ní, wọ́n sì pín owó tí wọ́n rí láàrin ara wọn, gẹ́gẹ́ bí ẹnìkọ̀ọ̀kan ti ṣe aláìní sí.

46 Wọ́n ń fi ọkàn kan lọ sí Tẹmpili lojoojumọ. Wọ́n jọ ń jẹun láti ilé dé ilé. Wọ́n jọ ń jẹun pẹlu ayọ̀ ati pẹlu ọkàn kan.

47 Wọ́n ń fi ìyìn fún Ọlọrun. Gbogbo àwọn eniyan ni ó fẹ́ràn wọn. Lojoojumọ ni àwọn tí wọ́n rí ìgbàlà ń dara pọ̀ mọ́ wọn.

Categories
ÌṢE ÀWỌN APOSTELI

ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 3

A Wo Arọ Kan Sàn Lẹ́nu Ọ̀nà Tẹmpili

1 Ní agogo mẹta ọ̀sán, Peteru ati Johanu gòkè lọ sí Tẹmpili ní àkókò adura.

2 Ọkunrin kan wà tí wọn máa ń gbé wá sibẹ, tí ó yarọ láti inú ìyá rẹ̀ wá. Lojoojumọ, wọn á máa gbé e wá sí ẹnu ọ̀nà Tẹmpili tí à ń pè ní “Ẹnu Ọ̀nà Dáradára,” kí ó lè máa ṣagbe lọ́dọ̀ àwọn tí ń wọ inú Tẹmpili lọ.

3 Nígbà tí ó rí Peteru ati Johanu tí wọ́n fẹ́ wọ inú Tẹmpili, ó ní kí wọ́n ta òun lọ́rẹ.

4 Peteru ati Johanu tẹjú mọ́ ọn, Peteru ní, “Wò wá!”

5 Ọkunrin náà bá ń wò wọ́n, ó ń retí pé wọn yóo fún òun ní nǹkan.

6 Peteru bá sọ fún un pé, “N kò ní fadaka tabi wúrà, ṣugbọn n óo fún ọ ní ohun tí mo ní. Ní orúkọ Jesu Kristi ti Nasarẹti, máa rìn.”

7 Ó bá fà á lọ́wọ́ ọ̀tún, ó gbé e dìde. Lẹsẹkẹsẹ ẹsẹ̀ rẹ̀ ati ọrùn-ẹsẹ̀ rẹ̀ bá mókun.

8 Ó bá fò sókè, ó dúró, ó sì ń rìn. Ó bá tẹ̀lé wọn wọ inú Tẹmpili; ó ń rìn, ó ń fò sókè, ó sì ń yin Ọlọrun.

9 Gbogbo àwọn eniyan rí i tí ó ń rìn, tí ó ń yin Ọlọrun.

10 Wọ́n ṣe akiyesi pé ẹni tí ó ti máa ń jókòó ṣagbe lẹ́nu Ọ̀nà Dáradára Tẹmpili ni. Ẹnu yà wọ́n, wọ́n ta gìrì sí ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí ọkunrin náà.

Ọ̀rọ̀ tí Peteru Sọ ní Ọ̀dẹ̀dẹ̀ Solomoni

11 Bí ọkunrin náà ti rọ̀ mọ́ Peteru ati Johanu, gbogbo àwọn eniyan sáré pẹlu ìyanu lọ sọ́dọ̀ wọn ní ọ̀dẹ̀dẹ̀ tí à ń pè ní ti Solomoni.

12 Nígbà tí Peteru rí wọn, ó bi àwọn eniyan pé, “Ẹ̀yin eniyan Israẹli, kí ló dé tí èyí fi yà yín lẹ́nu? Kí ló dé tí ẹ fi tẹjú mọ́ wa bí ẹni pé nípa agbára wa tabi nítorí pé a jẹ́ olùfọkànsìn ni a fi mú kí ọkunrin yìí rìn?

13 Ọlọrun Abrahamu, Ọlọrun Isaaki ati Ọlọrun Jakọbu, Ọlọrun àwọn baba wa ni ó dá Ọmọ rẹ̀, Jesu lọ́lá. Jesu yìí ni ẹ fi lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́, òun ni ẹ sẹ́ níwájú Pilatu nígbà tí ó fi dá a sílẹ̀.

14 Ẹ sẹ́ ẹni Ọlọrun ati olódodo, ẹ wá bèèrè pé kí wọ́n dá apànìyàn sílẹ̀ fun yín;

15 ẹ pa orísun ìyè. Òun yìí ni Ọlọrun jí dìde kúrò ninu òkú. Àwa gan-an ni ẹlẹ́rìí pé bẹ́ẹ̀ ló rí.

16 Orúkọ Jesu ati igbagbọ ninu orúkọ yìí ni ó mú ọkunrin tí ẹ rí yìí lára dá. Ẹ ṣá mọ̀ ọ́n. Igbagbọ ninu rẹ̀ ni ó fún ọkunrin yìí ní ìlera patapata, gẹ́gẹ́ bí gbogbo yín ti rí i fúnra yín.

17 “Ṣugbọn nisinsinyii, ará, mo mọ̀ pé ẹ kò mọ̀ọ́nmọ̀ ṣe é, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ìjòyè yín náà kò mọ̀ọ́nmọ̀ ṣe é.

18 Bẹ́ẹ̀ ni Ọlọrun ṣe mú ohun tí ó ti sọ tẹ́lẹ̀ láti ẹnu gbogbo àwọn wolii rẹ̀ ṣẹ, pé Mesaya òun níláti jìyà.

19 Nítorí náà, ẹ ronupiwada, kí ẹ yipada sọ́dọ̀ Ọlọrun bí ẹ bá fẹ́ kí á pa ẹ̀ṣẹ̀ yín rẹ́.

20 Nígbà náà, àkókò ìtura láti ọ̀dọ̀ Oluwa, yóo dé ba yín; Oluwa yóo wá rán Mesaya tí ó ti yàn tẹ́lẹ̀ si yín, èyí nnì ni Jesu,

21 ẹni tí ó níláti wà ní ọ̀run títí di àkókò tí ohun gbogbo yóo fi di titun, gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti sọ láti ìgbà àtijọ́, láti ẹnu àwọn wolii rẹ̀ mímọ́, àwọn eniyan ọ̀tọ̀.

22 Mose ṣá ti sọ pé, ‘Oluwa Ọlọrun yín yóo gbé wolii kan bí èmi dìde láàrin àwọn arakunrin yín. Òun ni kí ẹ gbọ́ràn sí lẹ́nu ninu ohun gbogbo tí ó bá sọ fun yín.

23 Ẹnikẹ́ni tí kò bá gbọ́ràn sí wolii náà lẹ́nu, píparun ni a óo pa á run patapata láàrin àwọn eniyan Ọlọrun.’

24 Gbogbo àwọn wolii, láti ìgbà Samuẹli ati àwọn tí ó dé lẹ́yìn rẹ̀, fi ohùn ṣọ̀kan sí ọ̀rọ̀ yìí, wọ́n ń sọ nípa àkókò yìí.

25 Ẹ̀yin gan-an ni ọmọ àwọn wolii; nítorí tiyín ni Ọlọrun ṣe bá àwọn baba yín dá majẹmu, nígbà tí ó sọ fún Abrahamu pé, ‘Nípa ọmọ rẹ ni n óo ṣe bukun gbogbo orílẹ̀-èdè ayé.’

26 Nígbà tí Ọlọrun gbé Ọmọ rẹ̀ dìde, ẹ̀yin ni ó kọ́kọ́ rán an sí, kí ó lè bukun yín láti mú kí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín yipada kúrò ní ọ̀nà burúkú rẹ̀.”

Categories
ÌṢE ÀWỌN APOSTELI

ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 4

A Mú Peteru ati Johanu Wá siwaju Ìgbìmọ̀ Àwọn Juu

1 Bí Peteru ti ń bá àwọn eniyan sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, Johanu wà lọ́dọ̀ rẹ̀, àwọn alufaa ati olórí àwọn ẹ̀ṣọ́ Tẹmpili ati àwọn Sadusi bá dé.

2 Inú bí wọn nítorí wọ́n ń kọ́ àwọn eniyan pé àwọn òkú yóo jí dìde. Wọ́n fi ajinde ti Jesu ṣe àpẹẹrẹ.

3 Wọ́n bá mú wọn, wọ́n tì wọ́n mọ́lé títí di ọjọ́ keji, nítorí ilẹ̀ ti ṣú.

4 Ṣugbọn ọ̀pọ̀ ninu àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà gbàgbọ́, iye wọn tó ẹgbẹẹdọgbọn (5,000) eniyan.

5 Nígbà tí ó di ọjọ́ keji, àwọn ìjòyè ati àwọn àgbààgbà ati àwọn amòfin péjọ ní Jerusalẹmu.

6 Anasi Olórí Alufaa ati Kayafa ati Johanu ati Alẹkisanderu ati àwọn ìdílé Olórí Alufaa wà níbẹ̀.

7 Wọ́n mú Peteru ati Johanu wá siwaju ìgbìmọ̀. Wọ́n wá bi wọ́n pé, “Irú agbára wo ni ẹ fi ṣe ohun tí ẹ ṣe yìí? Orúkọ ta ni ẹ lò?”

8 Nígbà náà ni Ẹ̀mí Mímọ́ wá fún Peteru ní agbára lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́, ó bá sọ fún wọn pé, “Ẹ̀yin ìjòyè láàrin àwọn eniyan ati ẹyin àgbààgbà,

9 bí ẹ bá ń wádìí lónìí nípa iṣẹ́ rere tí a ṣe fún ọkunrin aláìsàn yìí, bí ẹ bá fẹ́ mọ bí ara rẹ̀ ti ṣe dá,

10 ẹ jẹ́ kí ó hàn sí gbogbo yín ati gbogbo eniyan Israẹli pé, ọkunrin yìí dúró níwájú yín pẹlu ara líle nítorí orúkọ Jesu Kristi ará Nasarẹti, ẹni tí ẹ kàn mọ́ agbelebu, tí Ọlọrun jí dìde kúrò ninu òkú.

11 Jesu yìí ni

‘Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀ sílẹ̀,

tí ó wá di òkúta pataki igun-ilé.’

12 Kò sí ìgbàlà lọ́dọ̀ ẹlòmíràn; bẹ́ẹ̀ ni kò sí orúkọ mìíràn tí a fi fún eniyan lábẹ́ ọ̀run nípa èyí tí a lè fi gba eniyan là.”

13 Nígbà tí wọ́n rí ìgboyà Peteru ati ti Johanu, tí wọ́n wòye pé wọn kò mọ ìwé àtipé òpè eniyan ni wọ́n, ẹnu yà wọ́n. Wọ́n ṣe akiyesi wọn pé wọ́n ti wà pẹlu Jesu.

14 Wọ́n wo ọkunrin tí wọ́n mú lára dá tí ó dúró lọ́dọ̀ wọn, wọn kò sì mọ ohun tí wọn yóo sọ.

15 Wọ́n bá pàṣẹ pé kí wọ́n jáde kúrò lọ́dọ̀ àwọn ìgbìmọ̀. Àwọn ìgbìmọ̀ wá ń bi ara wọn pé,

16 “Kí ni a óo ṣe sí àwọn ọkunrin wọnyi o? Nítorí ó hàn lónìí sí gbogbo àwọn tí ó ń gbé Jerusalẹmu pé wọ́n ti ṣe iṣẹ́ abàmì. A kò sì lè wí pé èyí kò rí bẹ́ẹ̀.

17 Ṣugbọn kí ó má baà tún máa tàn kálẹ̀ sí i láàrin àwọn eniyan, ẹ jẹ́ kí á kìlọ̀ fún wọn pé wọn kò gbọdọ̀ dárúkọ Jesu fún ẹnikẹ́ni mọ́.”

18 Àwọn ìgbìmọ̀ bá tún pè wọ́n wọlé, wọ́n pàṣẹ fún wọn pé wọn kò gbọdọ̀ tún dárúkọ Jesu mọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò gbọdọ̀ tún fi orúkọ Jesu kọ́ àwọn eniyan mọ́.

19 Ṣugbọn Peteru ati Johanu dá wọn lóhùn pé, “Èwo ni ó tọ́ níwájú Ọlọrun: kí á gbọ́ràn si yín lẹ́nu ni, tabi kí á gbọ́ràn sí Ọlọrun lẹ́nu? Ẹ̀yin náà ẹ dà á rò.

20 Ní tiwa, a kò lè ṣe aláìsọ ohun tí a ti rí ati ohun tí a ti gbọ́.”

21 Lẹ́yìn tí wọ́n tún halẹ̀ mọ́ wọn, wọ́n dá wọn sílẹ̀, nítorí wọn kò rí ọ̀nà tí wọn ìbá fi jẹ wọ́n níyà, nítorí àwọn eniyan. Gbogbo eniyan ni wọ́n sì ń fi ìyìn fún Ọlọrun fún ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀.

22 Ọkunrin tí wọn ṣe iṣẹ́ abàmì ìmúláradá yìí lára rẹ̀ ju ẹni ogoji ọdún lọ.

Àwọn Onigbagbọ Gbadura fún Ìgboyà

23 Nígbà tí wọ́n dá wọn sílẹ̀, wọ́n lọ sọ́dọ̀ àwọn ẹgbẹ́ wọn, wọ́n ròyìn ohun gbogbo tí àwọn olórí alufaa ati àwọn àgbààgbà sọ fún wọn.

24 Nígbà tí wọ́n gbọ́, wọ́n jọ ké pe Ọlọrun pé, “Oluwa, ìwọ tí ó dá ọ̀run ati ayé ati òkun ati gbogbo ohun tí ó wà ninu wọn,

25 ìwọ tí ó sọ nípa Ẹ̀mí Mímọ́ láti ẹnu baba ńlá wa, Dafidi, ọmọ rẹ pé,

‘Kí ló dé tí àwọn orílẹ̀-èdè fi ń di rìkíṣí,

tí àwọn ará ilẹ̀ òkèèrè ń gbèrò asán?

26 Àwọn ọba ayé kó ara wọn jọ,

àwọn ìjòyè fohùn ṣọ̀kan,

láti dìtẹ̀ sí Oluwa ati sí Mesaya rẹ̀.’

27 Nítorí òdodo ni pé Hẹrọdu ati Pọntiu Pilatu pẹlu àwọn tí kì í ṣe Juu ati àwọn eniyan Israẹli péjọpọ̀ ní ìlú yìí, wọ́n ṣe ohun tí ó lòdì sí ọmọ mímọ́ rẹ, Jesu tí o ti fi òróró yàn ní Mesaya,

28 àwọn ohun tí ọwọ́ rẹ ati ètò rẹ ti ṣe ìlànà rẹ̀ tẹ́lẹ̀.

29 Ǹjẹ́ nisinsinyii, Oluwa, ṣe akiyesi bí wọ́n ti ń halẹ̀, kí o sì fún àwọn iranṣẹ rẹ ní ìgboyà ní gbogbo ọ̀nà láti lè sọ ọ̀rọ̀ rẹ.

30 Kí o wá na ọwọ́ rẹ kí o ṣe ìwòsàn, ṣe iṣẹ́ abàmì, ati iṣẹ́ ìyanu nípa orúkọ Jesu ọmọ mímọ́ rẹ.”

31 Bí wọ́n ti ń gbadura, ibi tí wọ́n péjọ sí mì tìtì, gbogbo wọn bá kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, wọ́n bá ń fi ìgboyà sọ ọ̀rọ̀ Ọlọrun.

Wọ́n Jọ Ní Ohun Gbogbo Ṣọ̀kan

32 Ọkàn kan ati ẹ̀mí kan ni gbogbo àwùjọ àwọn onigbagbọ ní. Kò sí ẹnìkan ninu wọn tí ó dá àwọn nǹkan tirẹ̀ yà sọ́tọ̀, wọ́n jọ ní gbogbo nǹkan papọ̀ ni.

33 Àwọn aposteli ń fi ẹ̀rí wọn hàn pẹlu agbára ńlá nípa ajinde Jesu Oluwa. Gbogbo àwọn eniyan sì ń bọlá fún wọn.

34 Kò sí ẹnikẹ́ni tí ó ṣe aláìní ohun kan láàrin wọn. Àwọn tí ó ní ilẹ̀ tabi ilé tà wọ́n, wọ́n mú owó tí wọ́n tà wọ́n wá,

35 wọ́n dà á sílẹ̀ níwájú àwọn aposteli kí wọ́n lè pín in fún àwọn tí ó bá ṣe aláìní.

36 Josẹfu, ọmọ ìdílé Lefi ará Kipru ẹni tí àwọn aposteli ń pè ní Banaba, (èyí ni “Ọmọ ìtùnú,”)

37 ní ilẹ̀ kan. Ó tà á, ó sì mú owó rẹ̀ wá fún àwọn aposteli.

Categories
ÌṢE ÀWỌN APOSTELI

ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 5

Ìtàn Anania ati Safira

1 Ọkunrin kan tí ń jẹ́ Anania pẹlu Safira, iyawo rẹ̀, ta ilẹ̀ kan.

2 Ọkunrin yìí yọ sílẹ̀ ninu owó tí wọ́n rí lórí rẹ̀, ó bá mú ìyókù wá siwaju àwọn aposteli. Iyawo rẹ̀ sì mọ̀ nípa rẹ̀.

3 Peteru bá bi í pé, “Anania, kí ló dé tí Satani fi gbà ọ́ lọ́kàn tí o fi ṣe èké sí Ẹ̀mí Mímọ́, tí o fi yọ sílẹ̀ ninu owó tí o rí lórí ilẹ̀ náà?

4 Kí o tó ta ilẹ̀ náà, mo ṣebí tìrẹ ni? Nígbà tí o tà á tán, mo ṣebí o ní àṣẹ lórí owó tí o tà á? Kí ló dé tí o gbèrò irú nǹkan yìí? Kì í ṣe eniyan ni o ṣèké sí, Ọlọrun ni.”

5 Nígbà tí Anania gbọ́ gbolohun yìí, ó ṣubú lulẹ̀, ó kú. Ẹ̀rù ńlá sì ba gbogbo àwọn tí wọ́n gbọ́.

6 Àwọn géńdé bá dìde, wọ́n fi aṣọ wé e, wọ́n gbé e lọ sin.

7 Nígbà tí ó tó bíi wakati mẹta lẹ́yìn náà, iyawo Anania wọlé dé. Kò mọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀.

8 Peteru bi í pé, “Sọ fún mi, ṣé iye tí ẹ ta ilẹ̀ náà nìyí?”

Ó dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, iye tí a tà á ni.”

9 Peteru bá bi í pé, “Kí ló dé tí ẹ jọ fi ohùn ṣọ̀kan láti dán Ẹ̀mí Oluwa wò? Wo ẹsẹ̀ àwọn tí wọ́n lọ sin ọkọ rẹ lẹ́nu ọ̀nà, wọn yóo gbé ìwọ náà jáde.”

10 Ni òun náà bá ṣubú lulẹ̀ lẹsẹkẹsẹ níwájú Peteru, ó bá kú. Àwọn géńdé bá wọlé, wọ́n rí òkú rẹ̀. Wọ́n bá gbé e jáde, wọ́n sì sin ín sí ẹ̀bá ọkọ rẹ̀.

11 Ẹ̀rù ńlá ba gbogbo ìjọ ati gbogbo àwọn tí ó gbọ́ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ wọnyi.

Àwọn Aposteli Ṣe Iṣẹ́ Abàmì Pupọ

12 Ọpọlọpọ iṣẹ́ abàmì ati iṣẹ́ ìyanu ni àwọn aposteli ṣe láàrin àwọn eniyan. Gbogbo wọn wà ní ìṣọ̀kan ní ọ̀dẹ̀dẹ̀ tí wọn ń pè ní ti Solomoni.

13 Kò sí ẹni tí ó láyà ninu àwọn ìyókù láti darapọ̀ mọ́ wọn. Ọ̀rọ̀ wọn níyì lọ́dọ̀ àwọn eniyan.

14 Àwọn tí wọ́n gba Oluwa gbọ́ túbọ̀ ń darapọ̀ mọ́ wọn, lọkunrin ati lobinrin.

15 Nígbà tí ó yá, àwọn eniyan a máa gbé àwọn aláìsàn wá sí títì lórí ẹní ati lórí ibùsùn, pé kí òjìji Peteru lè ṣíji bò wọ́n nígbà tí ó bá ń kọjá.

16 Ọpọlọpọ àwọn eniyan wá láti agbègbè ìlú Jerusalẹmu, wọ́n ń gbé àwọn aláìsàn ati àwọn tí ẹ̀mí burúkú ń dà láàmú wá; a sì mú gbogbo wọn lára dá.

A Ṣe Inúnibíni sí Àwọn Aposteli

17 Nígbà náà ni ẹ̀tanú gba ọkàn Olórí Alufaa ati gbogbo àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Sadusi tí ó wà pẹlu rẹ̀.

18 Wọ́n bá mú àwọn aposteli, wọ́n tì wọ́n mọ́lé ninu ilé ẹ̀wọ̀n ìgboro ìlú.

19 Nígbà tí ó di òru, angẹli Oluwa ṣí ìlẹ̀kùn ilé-ẹ̀wọ̀n, ó sìn wọ́n jáde, ó sọ fún wọn pé,

20 “Ẹ lọ dúró ninu Tẹmpili kí ẹ sọ gbogbo ọ̀rọ̀ ìyè yìí fún àwọn eniyan.”

21 Nígbà tí wọ́n gbọ́, wọ́n wọ inú Tẹmpili lọ nígbà tí ojúmọ́ mọ́, wọ́n bá ń kọ́ àwọn eniyan lẹ́kọ̀ọ́.

Nígbà tí Olórí Alufaa dé pẹlu àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, ó pe ìgbìmọ̀ ati gbogbo àwọn àgbààgbà láàrin àwọn ọmọ Israẹli jọ. Wọ́n bá ranṣẹ lọ sí inú ẹ̀wọ̀n kí wọn lọ mú àwọn aposteli náà wá.

22 Nígbà tí àwọn tí wọ́n rán dé ilé-ẹ̀wọ̀n, wọn kò rí wọn níbẹ̀. Wọ́n bá pada lọ jíṣẹ́ pé,

23 “A fojú wa rí ilé-ẹ̀wọ̀n ní títì, a bá àwọn tí wọn ń ṣọ́ ọ tí wọ́n dúró lẹ́nu ọ̀nà. Ṣugbọn nígbà tí a ṣílẹ̀kùn, tí a wọ inú ilé, a kò rí ẹnìkan.”

24 Nígbà tí ọ̀gá àwọn ẹ̀ṣọ́ ti Tẹmpili ati àwọn olórí alufaa gbọ́ ìròyìn yìí, ọkàn wọn dàrú; wọ́n ń ronú pé, irú kí ni eléyìí?

25 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹnìkan bá dé, wọ́n sọ fún wọn pé, “Àwọn ọkunrin tí ẹ tì mọ́lé wà ninu Tẹmpili, tí wọn ń kọ́ àwọn eniyan lẹ́kọ̀ọ́.”

26 Nígbà náà ni ọ̀gá àwọn ẹ̀ṣọ́ ati àwọn iranṣẹ lọ mú àwọn aposteli. Àwọn ẹ̀ṣọ́ náà kò fi ipá mú wọn, nítorí wọ́n bẹ̀rù àwọn eniyan kí àwọn eniyan má baà sọ wọ́n ní òkúta.

27 Wọ́n mú wọn wá siwaju ìgbìmọ̀. Olórí Alufaa wá bi wọ́n pé,

28 “Mo ṣebí a pàṣẹ fun yín pé kí ẹ má fi orúkọ yìí kọ́ ẹnikẹ́ni mọ́? Sibẹ gbogbo ará Jerusalẹmu ni ó ti gbọ́ nípa ẹ̀kọ́ yín yìí. Ẹ wá tún di ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ ọkunrin yìí lé wa lórí?”

29 Peteru pẹlu àwọn aposteli dáhùn pé, “A níláti gbọ́ ti Ọlọrun ju ti eniyan lọ.

30 Jesu tí ẹ̀yin pa, tí ẹ kàn mọ́ igi, Ọlọrun àwọn baba wa jí i dìde.

31 Òun ni Ọlọrun fi ṣe aṣiwaju ati olùgbàlà, tí ó gbé sí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, kí ó lè fi anfaani ìrònúpìwàdà ati ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ fún Israẹli.

32 Àwa gan-an ati Ẹ̀mí Mímọ́ tí Ọlọrun fi fún àwọn tí ó gbọ́ràn sí i lẹ́nu ni ẹlẹ́rìí àwọn ọ̀rọ̀ wọnyi.”

33 Ọ̀rọ̀ yìí gún àwọn tí ó gbọ́ ọ lọ́kàn tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi fẹ́ pa wọ́n.

34 Ṣugbọn Farisi kan ninu àwọn ìgbìmọ̀ dìde. Orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Gamalieli, olùkọ́ nípa ti òfin ni, ó lókìkí láàrin gbogbo àwọn eniyan. Ó ní kí àwọn ọkunrin náà jáde fún ìgbà díẹ̀.

35 Ó wá sọ fún àwọn ìgbìmọ̀ pé, “Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ ṣọ́ra nípa ohun tí ẹ fẹ́ ṣe sí àwọn ọkunrin yìí.

36 Nítorí nígbà kan, Tudasi kan dìde. Ó ní òun jẹ́ eniyan ńlá kan. Ó kó àwọn eniyan bí irinwo (400) jọ. Nígbà tó yá wọ́n pa á, wọ́n sì tú gbogbo àwọn tí ó ń tẹ̀lé e ká; gbogbo ọ̀tẹ̀ rẹ̀ sì jásí òfo.

37 Lẹ́yìn èyí, Judasi kan, ará Galili, dìde ní àkókò tí à ń kọ orúkọ àwọn eniyan sílẹ̀. Àwọn eniyan tẹ̀lé e. Ṣugbọn wọ́n pa á, wọ́n sì tú gbogbo àwọn tí ó ń tẹ̀lé e ká.

38 To ò, mo sọ fun yín o! Ẹ gáfárà fún àwọn ọkunrin yìí; ẹ fi wọ́n sílẹ̀ o! Bí ète yìí tabi ohun tí wọn ń ṣe bá jẹ́ láti ọwọ́ eniyan, yóo parẹ́.

39 Ṣugbọn bí ó bá jẹ́ láti ọwọ́ Ọlọrun ni, ẹ kò lè pa wọ́n run, ẹ óo kàn máa bá Ọlọrun jagun ni!”

Àwọn ìgbìmọ̀ rí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀.

40 Wọ́n bá pe àwọn aposteli wọlé, wọ́n nà wọ́n, wọ́n kìlọ̀ fún wọn pé wọn kò gbọdọ̀ fi orúkọ Jesu sọ̀rọ̀ mọ́. Wọ́n bá dá wọn sílẹ̀.

41 Wọ́n jáde kúrò níwájú ìgbìmọ̀, wọ́n ń yọ̀ nítorí a kà wọ́n yẹ kún àwọn tí a fi àbùkù kan nítorí orúkọ Jesu.

42 Lojoojumọ, ninu Tẹmpili ati láti ilé dé ilé, wọn kò dẹ́kun láti máa kọ́ eniyan ati láti máa waasu pé Jesu ni Mesaya.

Categories
ÌṢE ÀWỌN APOSTELI

ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 6

A Yan Àwọn Olùrànlọ́wọ́ Meje

1 Nígbà tí ó yá, tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu ń pọ̀ sí i, ìkùnsínú bẹ̀rẹ̀ láàrin àwọn tí ó ń sọ èdè Giriki ati àwọn tí ó ń sọ èdè Heberu, nítorí wọ́n ń fojú fo àwọn opó àwọn tí ń sọ èdè Giriki dá, nígbà tí wọ́n bá ń pín àwọn nǹkan ní ojoojumọ.

2 Àwọn aposteli mejila bá pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu yòókù jọ, wọ́n ní, “Kò yẹ kí á fi iṣẹ́ iwaasu ọ̀rọ̀ Ọlọrun sílẹ̀, kí á máa ṣe ètò oúnjẹ.

3 Nítorí náà, ẹ̀yin ará, ẹ wá ẹni meje láàrin yín, tí wọ́n ní orúkọ rere, tí wọ́n kún fún Ẹ̀mí Mímọ́ ati ọgbọ́n, kí á yàn wọ́n láti mójútó ètò yìí.

4 Àwa ní tiwa, a óo tẹra mọ́ adura gbígbà ati iṣẹ́ iwaasu ọ̀rọ̀ ìyìn rere.”

5 Ọ̀rọ̀ yìí dára lójú gbogbo àwùjọ, wọ́n bá yan Stefanu. Stefanu yìí jẹ́ onigbagbọ tọkàntọkàn, tí ó kún fún Ẹ̀mí Mímọ́. Wọ́n yan Filipi náà ati Prokoru ati Nikanọ ati Timoni ati Pamena ati Nikolausi ará Antioku tí ó ti gba ẹ̀sìn àwọn Juu.

6 Wọ́n kó wọn wá siwaju àwọn aposteli; wọ́n gbadura, wọ́n bá gbé ọwọ́ lé wọn lórí.

7 Ọ̀rọ̀ Ọlọrun wá ń gbilẹ̀. Iye àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu túbọ̀ ń pọ̀ sí i ní Jerusalẹmu. Pupọ ninu àwọn alufaa ni wọ́n sì di onigbagbọ.

Àwọn Aṣiwaju Àwọn Juu Mú Stefanu

8 Stefanu ń ṣe iṣẹ́ ìyanu ati iṣẹ́ abàmì ńlá láàrin àwọn eniyan nítorí pé ẹ̀bùn ati agbára Ọlọrun pọ̀ lọ́wọ́ rẹ̀.

9 Àwọn kan wá láti ilé ìpàdé kan tí à ń pè ní ti àwọn Olómìnira, ti àwọn ará Kurene ati àwọn ará Alẹkisandria; wọ́n tako Stefanu. Àwọn tí wọ́n wá láti Silisia ati láti Esia náà sì bẹ̀rẹ̀ sí bá a jiyàn.

10 Ṣugbọn wọn kò lè fèsì sí irú ọgbọ́n ati ẹ̀mí tí ó fi ń sọ̀rọ̀.

11 Wọ́n bá rú àwọn eniyan nídìí, láti sọ pé, “A gbọ́ nígbà tí ó ń sọ ìsọkúsọ sí Mose ati sí Ọlọrun.”

12 Wọ́n rú àwọn eniyan ati àwọn àgbààgbà ati àwọn amòfin nídìí, ni wọ́n bá mú un, wọ́n fà á lọ siwaju àwọn ìgbìmọ̀.

13 Wọ́n wá àwọn ẹlẹ́rìí èké tí wọ́n sọ pé, “Ọkunrin yìí kò yé sọ̀rọ̀ lòdì sí Tẹmpili mímọ́ yìí ati sí òfin Mose.

14 Nítorí a gbọ́ nígbà tí ó sọ pé Jesu ti Nasarẹti yóo wó ilé yìí, yóo yí àwọn àṣà tí Mose fún wa pada.”

15 Gbogbo àwọn tí ó jókòó ní ìgbìmọ̀ tẹjú mọ́ ọn, wọ́n rí ojú rẹ̀ tí ó dàbí ojú angẹli.

Categories
ÌṢE ÀWỌN APOSTELI

ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 7

Ọ̀rọ̀ Tí Stefanu Sọ

1 Olórí Alufaa bá bi í pé, “Ṣé bẹ́ẹ̀ ni ọ̀ràn náà rí?”

2 Stefanu bá tẹnu bọ̀rọ̀, ó ní, “Ẹ̀yin arakunrin ati baba mi, ẹ gbọ́ ohun tí mo ní sọ. Ọlọrun Ológo farahàn fún baba wa, Abrahamu, nígbà tí ó ṣì wà ní ilẹ̀ Mesopotamia, kí ó tó wá máa gbé ilẹ̀ Kenaani.

3 Ó sọ fún un pé, ‘Jáde kúrò ní ilẹ̀ rẹ, láàrin àwọn ẹbí rẹ, kí o lọ sí ilẹ̀ tí èmi yóo fihàn ọ́.’

4 Ó bá jáde kúrò ní ilẹ̀ Kalidea láti máa gbé Kenaani. Nígbà tí baba rẹ̀ kú, ó kúrò níbẹ̀ láti wá máa gbé ilẹ̀ yìí, níbi tí ẹ̀ ń gbé nisinsinyii.

5 Ní àkókò náà, Ọlọrun kò fún un ní ogún ninu ilẹ̀ náà, bí ó tilẹ̀ ṣe ẹsẹ̀ bàtà kan, kò ní níbẹ̀. Ṣugbọn Ọlọrun ṣe ìlérí láti fún òun ati ọmọ rẹ̀ tí yóo gbẹ̀yìn rẹ̀ ní ilẹ̀ náà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò ní ọmọ ní àkókò náà.

6 Ọlọrun sọ fún un pé, ‘Àwọn ọmọ rẹ yóo jẹ́ àlejò ní ilẹ̀ àjèjì. Àwọn eniyan ibẹ̀ yóo lò wọ́n bí ẹrú, wọn óo pọ́n wọn lójú fún irinwo (400) ọdún.

7 Ṣugbọn orílẹ̀-èdè tí ó lò wọ́n bí ẹrú ni Èmi yóo dá lẹ́jọ́. Lẹ́yìn náà wọn yóo jáde kúrò ní ilẹ̀ àjèjì náà, wọn óo sì sìn mí ní ilẹ̀ yìí.’

8 Ọlọrun wá bá a dá majẹmu, ó fi ilà kíkọ ṣe àmì majẹmu náà. Nígbà tí ó bí Isaaki, ó kọ ọ́ nílà ní ọjọ́ kẹjọ. Isaaki bí Jakọbu. Jakọbu bí àwọn baba-ńlá wa mejila.

9 “Àwọn baba-ńlá wa jowú Josẹfu, wọ́n tà á lẹ́rú sí ilẹ̀ Ijipti. Ṣugbọn Ọlọrun wà pẹlu rẹ̀.

10 Ọlọrun yọ ọ́ kúrò ninu gbogbo ìpọ́njú tí ó rí. Nígbà tí ó yọ siwaju Farao, ọba Ijipti, Ọlọrun fún un lọ́gbọ́n, ó sì jẹ́ kí ó rí ojú àánú ọba Ijipti. Farao bá fi jẹ gomina lórí gbogbo ilẹ̀ Ijipti ati lórí ààfin ọba.

11 Nígbà tí ó yá, ìyàn mú ní gbogbo ilẹ̀ Ijipti ati ní ilẹ̀ Kenaani. Eléyìí mú ìṣòro pupọ wá. Àwọn eniyan wa kò bá rí oúnjẹ jẹ.

12 Nígbà tí Jakọbu gbọ́ pé oúnjẹ wà ní Ijipti, ó kọ́kọ́ rán àwọn baba wa lọ.

13 Ní ẹẹkeji ni àwọn arakunrin rẹ̀ tó mọ ẹni tí Josẹfu jẹ́. A sì fi ìdílé Josẹfu han Farao.

14 Josẹfu bá ranṣẹ láti pe Jakọbu baba rẹ̀ wá ati gbogbo àwọn ẹbí rẹ̀. Wọ́n jẹ́ eniyan marunlelaadọrin (75).

15 Jakọbu bá lọ sí Ijipti. Níbẹ̀ ni ó kú sí, òun ati àwọn baba wa náà.

16 Wọ́n gbé òkú wọn lọ sí Ṣekemu, wọ́n sin wọ́n sinu ibojì tí Abrahamu fowó rà lọ́wọ́ àwọn ọmọ Hamori ní Ṣekemu.

17 “Nígbà tí ó fẹ́rẹ̀ tó àkókò tí ìlérí tí Ọlọrun ṣe fún Abrahamu yóo ṣẹ, àwọn eniyan náà wá túbọ̀ ń pọ̀ níye ní Ijipti.

18 Nígbà tó yá, ọba mìíràn tí kò mọ Josẹfu jẹ ní ilẹ̀ Ijipti.

19 Ọba yìí bá fi ọgbọ́n àrékérekè bá orílẹ̀-èdè wa lò. Ó dá àwọn baba wa lóró, ó mú kí wọ́n máa sọ ọmọ nù, kí wọ́n baà lè kú.

20 Ní àkókò yìí ni a bí Mose. Ó dára lọ́mọ pupọ. Àwọn òbí rẹ̀ tọ́ ọ fún oṣù mẹta ninu ilé baba rẹ̀

21 Nígbà tí wọ́n sọ ọ́ nù, ni ọmọ Farao, obinrin, bá tọ́ ọ gẹ́gẹ́ bí ọmọ ti ara rẹ̀.

22 Gbogbo ọgbọ́n àwọn ará Ijipti ni wọ́n fi kọ́ Mose. Ati ọ̀rọ̀ sísọ, ati iṣẹ́ ṣíṣe kò sí èyí tí kò mọ̀ ọ́n ṣe.

23 “Nígbà tí Mose di ẹni ogoji ọdún, ó pinnu pé òun yóo lọ bẹ àwọn ará òun, àwọn ọmọ Israẹli, wò.

24 Ó bá rí ọ̀kan ninu àwọn ará rẹ̀ tí ará Ijipti ń jẹ níyà. Ó bá lọ gbà á sílẹ̀. Ó gbẹ̀san ìyà tí wọ́n ti fi jẹ ẹ́, ó lu ará Ijipti náà pa.

25 Ó rò pé yóo yé àwọn arakunrin òun pé Ọlọrun yóo ti ọwọ́ òun fún wọn ní òmìnira. Ṣugbọn kò yé wọn bẹ́ẹ̀.

26 Nígbà tí ó di ọjọ́ keji, ó yọ sí àwọn kan tí wọn ń jà. Ó bá ní kí òun parí ìjà fún wọn. Ó ní, ‘Ẹ̀yin ará, arakunrin ara yín ni ẹ̀ ń ṣe. Kí ló dé tí ẹ̀ ń lu ara yín?’

27 Ẹni tí ó jẹ̀bi tì í sẹ́yìn, ó ní, ‘Ta ni fi ọ́ ṣe olórí ati onídàájọ́ lórí wa?

28 Ṣé o fẹ́ pa mí bí o ti ṣe pa ará Ijipti lánàá ni?’

29 Nígbà tí Mose gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ó sálọ. Ó ń lọ gbé ilẹ̀ Midiani. Ó bí ọmọ meji níbẹ̀.

30 “Lẹ́yìn ogoji ọdún, angẹli kán yọ sí i ninu ìgbẹ́ tí ń jóná ní aṣálẹ̀ lẹ́bàá òkè Sinai.

31 Nígbà tí Mose rí ìran náà, ẹnu yà á. Nígbà tí ó súnmọ́ ọn pé kí òun wò ó fínnífínní, ó gbọ́ ohùn Oluwa tí ó sọ pé,

32 ‘Èmi ni Ọlọrun àwọn baba rẹ, Ọlọrun Abrahamu, Ọlọrun Isaaki, ati ti Jakọbu.’ Mose bá bẹ̀rẹ̀ sí gbọ̀n. Kò tó ẹni tí í wò ó.

33 Oluwa tún sọ fún un pé, ‘Bọ́ sálúbàtà tí ó wà lẹ́sẹ̀ rẹ, nítorí ilẹ̀ mímọ́ ni ibi tí o dúró sí.

34 Mo ti rí gbogbo ìrora tí àwọn eniyan mi ń jẹ ní Ijipti. Mo ti gbọ́ ìkérora wọn, mo sì ṣetán láti yọ wọ́n. Ó yá nisinsinyii. N óo rán ọ lọ sí Ijipti.’

35 “Mose yìí kan náà, tí wọ́n kọ̀, tí wọ́n sọ fún pé, ‘Ta ni ó fi ọ́ ṣe olórí ati onídàájọ́?’ Òun ni Ọlọrun rán angẹli sí, tí ó farahàn án ninu ìgbẹ́ tí ń jó, láti jẹ́ olórí ati olùdáǹdè.

36 Mose yìí ni aṣaaju wọn, tí ó ṣe iṣẹ́ ìyanu ati iṣẹ́ abàmì ní ilẹ̀ Ijipti ní Òkun Pupa ati ní ilẹ̀ aṣálẹ̀ fún ogoji ọdún.

37 Mose yìí ni ó sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, ‘Ọlọrun yóo gbé wolii kan bí èmi dìde fun yín láàrin àwọn arakunrin yín.’

38 Mose náà ni ó bá angẹli sọ̀rọ̀ ní òkè Sinai nígbà tí wọ́n wà ninu àwùjọ ní aṣálẹ̀, tí ó tún bá àwọn baba wa sọ̀rọ̀. Òun ni ó gba ọ̀rọ̀ ìyè láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun tí ó fi fún wa.

39 “Ṣugbọn àwọn baba wa kò fẹ́ gba ọ̀rọ̀ rẹ̀ gbọ́. Wọ́n tì í kúrò lọ́dọ̀ wọn; ọkàn wọn tún pada sí Ijipti.

40 Wọ́n sọ fún Aaroni pé, ‘Ṣe oriṣa fún wa kí á rí ohun máa bọ, kí ó máa tọ́ wa sí ọ̀nà. A kò mọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí Mose tí ó kó wa jáde láti ilẹ̀ Ijipti.’

41 Wọ́n bá ṣe ère ọmọ mààlúù kan ní àkókò náà, wọ́n rúbọ sí i. Wọ́n bá ń ṣe àríyá lórí ohun tí wọ́n fi ọwọ́ wọn ṣe.

42 Ọlọrun bá pada lẹ́yìn wọn, ó fi wọ́n sílẹ̀ láti máa sin ìràwọ̀ ojú ọ̀run, gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀ ninu ìwé àwọn wolii pé,

‘Ẹ̀yin ọmọ Israẹli,

ǹjẹ́ ẹ mú ẹran wá fi rúbọ sí mi fún ogoji ọdún ní aṣálẹ̀?

43 Ṣebí àtíbàbà Moleki ni ẹ gbé rù,

ati ìràwọ̀ Refani oriṣa yín,

àwọn ère tí ẹ ṣe láti máa foríbalẹ̀ fún?

N óo le yín lọ sí ìgbèkùn, ẹ óo kọjá Babiloni.’

44 “Àwọn baba wa ní àgọ́ ẹ̀rí kan ní aṣálẹ̀. Ọlọrun bá Mose sọ̀rọ̀, ó sì pàṣẹ fún un pé kí ó ṣe àgọ́ yìí gẹ́gẹ́ bí àwòrán tí òun ti fihàn án tẹ́lẹ̀.

45 Àwọn baba wa tí wọ́n tẹ̀lé Joṣua gba ilẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè tí Ọlọrun lé kúrò níwájú wọn, lẹ́yìn náà wọ́n gbé àgọ́ náà wá. Àgọ́ yìí sì wà pẹlu wa títí di àkókò Dafidi.

46 Dafidi bá ojurere Ọlọrun pàdé; ó wá bèèrè pé kí Ọlọrun jẹ́ kí òun kọ́ ilé fún òun, Ọlọrun Jakọbu.

47 Ṣugbọn Solomoni ni ó kọ́ ilé fún un.

48 “Bẹ́ẹ̀ ni Ọba tí ó ga jùlọ kì í gbé ilé tí a fi ọwọ́ kọ́. Gẹ́gẹ́ bí wolii nì ti sọ:

49 ‘Ọ̀run ni ìtẹ́ mi, ayé ni tìmùtìmù ìtìsẹ̀ mi.

Irú ilé wo ni ẹ̀ báà kọ́ fún mi?

Bẹ́ẹ̀ ni Oluwa wí.

Níbo ni ẹ̀ báà palẹ̀ mọ́ fún mi pé kí n ti máa sinmi?

50 Ṣebí èmi ni mo fọwọ́ mi ṣe gbogbo nǹkan wọnyi?’

51 “Ẹ̀yin olóríkunkun, ọlọ́kàn líle, elétí dídi wọnyi! Nígbà gbogbo ni ẹ̀ ń tako Ẹ̀mí Mímọ́. Bí àwọn baba yín ti rí, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin náà rí.

52 Èwo ninu àwọn wolii ni àwọn Baba yín kò ṣe inúnibíni sí? Wọ́n pa àwọn tí wọ́n sọtẹ́lẹ̀ pé Ẹni olódodo yóo dé. Ní àkókò yìí ẹ wá dìtẹ̀ sí i, ẹ ṣe ikú pa á.

53 Ẹ̀yin yìí ni ẹ gba òfin Ọlọrun láti ọwọ́ àwọn angẹli, ṣugbọn ẹ kò pa òfin náà mọ́.”

Wọ́n Sọ Stefanu ní Òkúta Pa

54 Nígbà tí wọ́n gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ yìí, ó gún wọn lọ́kàn. Wọ́n bá pòṣé sí i.

55 Ṣugbọn Ẹ̀mí Mímọ́ gbé Stefanu, ó tẹ ojú mọ́ òkè ọ̀run, ó rí ògo Ọlọrun, ó tún rí Jesu tí ó dúró lọ́wọ́ ọ̀tún Ọlọrun.

56 Ó bá dáhùn pé, “Ẹ wò ó, mo rí ojú ọ̀run tí ó pínyà. Mo wá rí Ọmọ-Eniyan tí ó dúró lọ́wọ́ ọ̀tún Ọlọrun.”

57 Ni wọ́n bá kígbe, wọ́n fi ọwọ́ di etí, gbogbo wọ́n rọ́ lù ú;

58 wọ́n fà á jáde lọ sí ẹ̀yìn ìlú, wọ́n bá ń sọ ọ́ ní òkúta. Àwọn ẹlẹ́rìí fi ẹ̀wù wọn lélẹ̀ níwájú ọdọmọkunrin kan tí à ń pè ní Saulu.

59 Bí wọ́n ti ń sọ òkúta lu Stefanu, ó ké pe Jesu Oluwa, ó ní, “Oluwa Jesu, gba ẹ̀mí mi.”

60 Ni ó bá kúnlẹ̀, ó kígbe, ó ní, “Oluwa, má ṣe ka ẹ̀ṣẹ̀ yìí sí wọn lọ́rùn.” Nígbà tí ó sọ báyìí tán, ó kú.

Categories
ÌṢE ÀWỌN APOSTELI

ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 8

1 Saulu bá wọn lọ́wọ́ sí ikú rẹ̀.

Saulu Ṣe Inúnibíni Sí Ìjọ Kristi

Láti ọjọ́ náà ni inúnibíni ńlá ti bẹ̀rẹ̀ sí ìjọ tí ó wà ní Jerusalẹmu. Gbogbo àwọn onigbagbọ bá túká lọ sí gbogbo agbègbè Judia ati Samaria. Àwọn aposteli nìkan ni kò kúrò ní ìlú.

2 Àwọn olùfọkànsìn sin òkú Stefanu, wọ́n sì ṣọ̀fọ̀ pupọ lórí rẹ̀.

3 Ṣugbọn Saulu bẹ̀rẹ̀ sí da ìjọ rú. Ó ń wọ ojúlé kiri, ó ń fa tọkunrin tobinrin jáde, lọ sẹ́wọ̀n.

A Waasu Ìyìn Rere ní Samaria

4 Àwọn tí wọ́n túká bá ń lọ káàkiri, wọ́n ń waasu ọ̀rọ̀ náà.

5 Filipi lọ sí ìlú Samaria kan, ó waasu fún wọn nípa Kristi.

6 Àwọn eniyan ṣù bo Filipi kí wọ́n lè gbọ́ ọ̀rọ̀ tí ó ń sọ, wọ́n sì ń rí iṣẹ́ abàmì tí ó ń ṣe.

7 Nítorí àwọn ẹ̀mí burúkú ń lọgun bí wọ́n ti ń jáde kúrò ninu ọpọlọpọ eniyan. Bẹ́ẹ̀ ni a mú ọpọlọpọ àwọn arọ ati àwọn tí wọ́n ní àbùkù ara lára dá.

8 Inú àwọn eniyan dùn pupọ ní ìlú náà.

9 Ọkunrin kán wà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Simoni, tí ó ti máa ń pidán ní ìlú náà. Èyí jẹ́ ìyanu fún àwọn ará Samaria, wọ́n ní ẹni ńlá ni ọkunrin náà.

10 Gbogbo eniyan ló kà á kún; ati àwọn eniyan yẹpẹrẹ ati àwọn eniyan pataki wọn. Wọ́n ní, “Eléyìí ní agbára Ọlọrun tí à ń pè ní ‘Agbára ńlá.’ ”

11 Tẹ́lẹ̀ rí òun ni àwọn eniyan kà kún, tí idán tí ó ń pa ń yà wọ́n lẹ́nu.

12 Ṣugbọn nígbà tí wọ́n gba ìyìn rere tí Filipi waasu nípa ìjọba Ọlọrun ati orúkọ Jesu Kristi gbọ́, tọkunrin tobinrin wọn ṣe ìrìbọmi.

13 Simoni náà gbàgbọ́, ó ṣe ìrìbọmi, ni ó bá fara mọ́ Filipi. Nígbà tí ó rí iṣẹ́ abàmì ati iṣẹ́ ìyanu ńlá tí ó ń ṣe, ẹnu yà á.

14 Àwọn aposteli tí ó wà ní Jerusalẹmu gbọ́ bí àwọn ará Samaria ti gba ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Wọ́n bá rán Peteru ati Johanu sí wọn.

15 Nígbà tí wọ́n dé, wọ́n gbadura fún wọn kí wọ́n lè gba Ẹ̀mí Mímọ́,

16 nítorí Ẹ̀mí Mímọ́ kò ì tíì bà lé ẹnikẹ́ni ninu wọn. Ìrìbọmi ní orúkọ Oluwa Jesu nìkan ni wọ́n ṣe.

17 Lẹ́yìn tí Peteru ati Johanu ti gbé ọwọ́ lé wọn, wọ́n bá gba Ẹ̀mí Mímọ́.

18 Nígbà tí Simoni rí i pé ọwọ́ tí àwọn aposteli gbé lé wọn ni ó mú kí wọ́n rí Ẹ̀mí gbà, ó fi owó lọ̀ wọ́n.

19 Ó ní, “Ẹ fún mi ní irú àṣẹ yìí kí ẹni tí mo bá gbé ọwọ́ lé, lè gba Ẹ̀mí Mímọ́.”

20 Ṣugbọn Peteru sọ fún un pé, “Ìwọ ati owó rẹ yóo ṣègbé! O rò pé o lè fi owó ra ẹ̀bùn Ọlọrun.

21 O kò ní ipa tabi ìpín ninu ọ̀rọ̀ yìí, nítorí ọkàn rẹ kò tọ́ níwájú Ọlọrun.

22 Nítorí náà, ronupiwada kúrò ninu ohun burúkú yìí, kí o tún bẹ Oluwa kí ó dárí èrò ọkàn rẹ yìí jì ọ́.

23 Nítorí mo wòye pé ẹ̀tanú ti gbà ọ́ lọ́kàn, àtipé aiṣododo ti dè ọ́ lẹ́wọ̀n.”

24 Simoni dá Peteru lóhùn pé, “Ẹ gbadura sí Oluwa fún mi kí ohunkohun tí ẹ wí má ṣẹlẹ̀ sí mi.”

25 Lẹ́yìn tí Peteru ati Johanu ti jẹ́rìí tí wọ́n ti sọ ọ̀rọ̀ Oluwa tán, wọ́n pada sí Jerusalẹmu. Wọ́n ń waasu ìyìn rere ní ọpọlọpọ àwọn abúlé ilẹ̀ Samaria bí wọ́n ti ń pada lọ.

Filipi ati Ìwẹ̀fà Ará Etiopia

26 Angẹli Oluwa sọ fún Filipi pé, “Dìde kí o lọ sí apá gúsù, ní ọ̀nà tí ó lọ láti Jerusalẹmu sí Gasa.” (Aṣálẹ̀ ni ọ̀nà yìí gbà lọ.)

27 Ni Filipi bá dìde lọ. Ó bá rí ọkunrin ará Etiopia kan. Ó jẹ́ ìwẹ̀fà onípò gíga kan lábẹ́ Kandake, ọbabinrin Etiopia. Òun ni akápò ìjọba. Ó ti lọ ṣe ìsìn ní Jerusalẹmu,

28 ó wá ń pada lọ sílé. Ó jókòó ninu ọkọ̀ ẹlẹ́ṣin rẹ̀, ó ń ka ìwé wolii Aisaya.

29 Ẹ̀mí sọ fún Filipi pé, “Lọ síbi ọkọ nnì kí o súnmọ́ ọn.”

30 Nígbà tí Filipi sáré, tí ó súnmọ́ ọn, ó gbọ́ tí ó ń ka ìwé wolii Aisaya. Ó bi í pé, “Ǹjẹ́ ohun tí ò ń kà yé ọ?”

31 Ó dáhùn pé, “Ó ṣe lè yé mi láìjẹ́ pé ẹnìkan bá ṣe àlàyé rẹ̀ fún mi?” Ó bá bẹ Filipi pé kí ó gòkè wọ inú ọkọ̀, kí ó jókòó ti òun.

32 Apá ibi tí ó ń kà nìyí:

“Bí aguntan tí a mú lọ sí ilé ìpẹran,

tí à ń fà níwájú àwọn tí ń rẹ́ irun rẹ̀,

kò fọhùn, bẹ́ẹ̀ ni kò ya ẹnu rẹ̀.

33 A rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀. A kò ṣe ẹ̀tọ́ nípa ọ̀ràn rẹ̀.

Ẹnikẹ́ni kò ní lè sọ nípa ìran rẹ̀.

Nítorí a pa á run kúrò lórí ilẹ̀ alààyè.”

34 Ìwẹ̀fà náà sọ fún Filipi pé, “Mo bẹ̀ ọ́, ọ̀rọ̀ ta ni wolii Ọlọrun yìí ń sọ, ọ̀rọ̀ ara rẹ̀ ni tabi ọ̀rọ̀ ẹlòmíràn?”

35 Filipi bá tẹnu bọ ọ̀rọ̀. Ó bẹ̀rẹ̀ láti ibi àkọsílẹ̀ yìí, ó waasu ìyìn rere Jesu fún un.

36 Bí wọn tí ń lọ lọ́nà, wọ́n dé odò kan. Ìwẹ̀fà náà sọ pé, “Wo omi. Kí ló dé tí o ò fi kúkú rì mí bọmi?” [

37 Filipi sọ fún un pé, “Bí o bá gbàgbọ́ tọkàntọkàn, ẹ̀tọ́ ni.” Ó dáhùn pé, “Mo gbàgbọ́ pé Ọmọ Ọlọrun ni Jesu Kristi.”]

38 Ìwẹ̀fà náà bá pàṣẹ pé kí ọkọ̀ dúró. Òun ati Filipi bá sọ̀kalẹ̀, wọ́n lọ sinu odò, Filipi bá rì í bọmi.

39 Nígbà tí wọ́n jáde kúrò ninu odò. Ẹ̀mí Oluwa gbé Filipi lọ, ìwẹ̀fà náà kò sì rí i mọ́. Ó bá ń bá ọ̀nà rẹ̀ lọ pẹlu ayọ̀.

40 Ní Asotu ni a tún ti rí Filipi. Ó ń waasu ní gbogbo àwọn ìlú tí ó gbà kọjá títí ó fi dé Kesaria.

Categories
ÌṢE ÀWỌN APOSTELI

ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 9

Saulu di Onigbagbọ

1 Ní gbogbo àkókò yìí, Saulu ń fi ikú dẹ́rùba àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Oluwa. Ó lọ sọ́dọ̀ Olórí Alufaa,

2 ó gba ìwé lọ́dọ̀ rẹ̀ láti lọ sí àwọn ilé ìpàdé tí ó wà ní Damasku. Ìwé yìí fún un ní àṣẹ pé bí ó bá rí àwọn tí ń tẹ̀lé ọ̀nà ẹ̀sìn yìí, ìbáà ṣe ọkunrin ìbáà ṣe obinrin, kí ó dè wọ́n, kí ó sì fà wọ́n wá sí Jerusalẹmu.

3 Bí ó ti ń lọ lọ́nà, tí ó súnmọ́ Damasku, iná kan mọ́lẹ̀ yí i ká lójijì;

4 ó bá ṣubú lulẹ̀. Ó wá gbọ́ ohùn ẹnìkan tí ó bi í pé, “Saulu! Saulu! Kí ló dé tí o fi ń ṣe inúnibíni sí mi?”

5 Saulu bèèrè pé, “Ta ni ọ́, Oluwa?”

Ẹni náà bá dáhùn pé, “Èmi ni Jesu, ẹni tí ò ń ṣe inúnibíni sí.

6 Dìde nisinsinyii, kí o wọ inú ìlú lọ. A óo sọ ohun tí o níláti ṣe fún ọ.”

7 Àwọn ọkunrin tí ó ń bá a rìn dúró. Wọn kò sọ ohunkohun. Wọ́n ń gbọ́ ohùn eniyan, ṣugbọn wọn kò rí ẹnìkankan.

8 Saulu bá dìde nílẹ̀, ó la ojú sílẹ̀ ṣugbọn kò ríran. Wọ́n bá fà á lọ́wọ́ lọ sí Damasku.

9 Fún ọjọ́ mẹta, kò ríran, kò jẹ, bẹ́ẹ̀ ni kò mu.

10 Ọmọ-ẹ̀yìn Jesu kan wà ní Damasku tí ń jẹ́ Anania. Oluwa pè é ní ojú ìran, ó ní, “Anania!”

Anania bá dáhùn pé, “Èmi nìyí, Oluwa.”

11 Oluwa bá sọ fún un pé, “Dìde. Lọ sí títì tí à ń pè ní ‘Títì títọ́,’ ní ilé Judasi kí o bèèrè ẹni tí ó ń jẹ́ Saulu, ará Tasu. O óo bá a ní ibi tí ó gbé ń gbadura.

12 Ní ojú ìran, ó rí ọkunrin kan tí ń jẹ́ Anania, tí ó wọlé tọ̀ ọ́ lọ, tí ó fi ọwọ́ bà á lójú kí ó lè tún ríran.”

13 Anania dáhùn pé, “Oluwa, mo ti gbọ́ ọ̀rọ̀ ọkunrin yìí lẹ́nu ọpọlọpọ eniyan: oríṣìíríṣìí ibi ni ó ti ṣe sí àwọn eniyan mímọ́ rẹ ní Jerusalẹmu.

14 Wíwá tí ó tún wá síhìn-ín, ó wá pẹlu àṣẹ láti ọ̀dọ̀ àwọn olórí alufaa láti de gbogbo àwọn tí ó ń pe orúkọ rẹ ni.”

15 Oluwa sọ fún un pé, “Lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, nítorí mo ti yàn án láti mú orúkọ mi lọ siwaju àwọn orílẹ̀-èdè yòókù ati àwọn ọba wọn ati àwọn ọmọ Israẹli.

16 N óo fi oríṣìíríṣìí ìyà tí ó níláti jẹ nítorí orúkọ mi hàn án.”

17 Anania bá lọ, ó wọ inú ilé náà, ó fi ọwọ́ kan Saulu. Ó ní, “Saulu arakunrin mi, Oluwa ni ó rán mi sí ọ. Jesu tí ó farahàn ọ́ ní ojú ọ̀nà tí o gbà wá, ni ó rán mi wá, kí o lè tún ríran, kí o sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́.”

18 Lẹsẹkẹsẹ nǹkankan bọ́ sílẹ̀ lójú rẹ̀ bí ìpẹ́pẹ́, ó sì tún ríran. Ó dìde, ó bá gba ìrìbọmi.

19 Ó bá jẹun, ara rẹ̀ bá tún mókun. Ó wà pẹlu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu tí ó wà ní Damasku fún ọjọ́ díẹ̀.

20 Láì jáfara ó bẹ̀rẹ̀ sí waasu ninu ilé ìpàdé àwọn Juu pé Jesu ni Ọmọ Ọlọrun.

21 Ẹnu ya gbogbo àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀. Wọ́n ní “Ará ibí yìí kọ́ ni ó ń pa àwọn tí ó ń pe orúkọ yìí ní Jerusalẹmu, tí ó tún wá síhìn-ín láti fi ẹ̀wọ̀n dè wọ́n, tí ó fẹ́ fà wọ́n lọ sọ́dọ̀ àwọn olórí alufaa?”

22 Ṣugbọn ńṣe ni Saulu túbọ̀ ń lágbára sí i. Àwọn Juu tí ó ń gbé Damasku kò mọ ohun tí wọ́n le wí mọ́, nítorí ó fi ẹ̀rí hàn pé Jesu ni Mesaya.

Saulu Bọ́ lọ́wọ́ Àwọn Juu

23 Bí ọjọ́ tí ń gorí ọjọ́ àwọn Juu gbèrò pọ̀ bí wọn yóo ti ṣe pa á.

24 Ṣugbọn Saulu gbọ́ nípa ète wọn. Wọ́n ń ṣọ́ àwọn ẹnu odi ìlú tọ̀sán-tòru kí wọ́n baà lè pa á.

25 Ṣugbọn ní alẹ́ ọjọ́ kan, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ gbé e sinu apẹ̀rẹ̀, wọ́n sì sọ̀ ọ́ kalẹ̀ láti orí odi ìlú.

Saulu Pada Dé Jerusalẹmu

26 Nígbà tí Saulu dé Jerusalẹmu, ó fẹ́ darapọ̀ mọ́ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu. Ṣugbọn ẹ̀rù rẹ̀ ń bà wọ́n; wọn kò gbàgbọ́ pé ó ti di ọmọ-ẹ̀yìn Jesu.

27 Ṣugbọn Banaba mú un lọ sọ́dọ̀ àwọn aposteli, ó ròyìn fún wọn bí ó ti rí Oluwa lọ́nà, bí Oluwa ti bá a sọ̀rọ̀, ati bí ó ti fi ìgboyà waasu lórúkọ Jesu ní Damasku.

28 Ó bá ń bá wọn gbé ní Jerusalẹmu, ó ń wọlé, ó ń jáde, ó ń fi ìgboyà waasu lórúkọ Oluwa,

29 ó ń bá àwọn Juu tí ó ń sọ èdè Giriki jiyàn. Ṣugbọn wọ́n gbèrò láti pa á.

30 Nígbà tí àwọn onigbagbọ mọ̀, wọ́n sìn ín lọ sí Kesaria, wọ́n fi ranṣẹ sí Tasu.

31 Gbogbo ìjọ ní Judia, ati Galili, ati Samaria wà ní alaafia, wọ́n sì fìdí múlẹ̀. Wọ́n ń gbé ìgbé-ayé wọn pẹlu ìbẹ̀rù Oluwa, wọ́n sì ń pọ̀ sí i nípa ìrànlọ́wọ́ Ẹ̀mí Mímọ́.

Peteru Mú Iniasi Láradá

32 Bí Peteru tí ń lọ káàkiri láti ibìkan dé ibi keji, ó dé ọ̀dọ̀ àwọn eniyan Ọlọrun tí wọn ń gbé ìlú Lida.

33 Ó rí ọkunrin kan níbẹ̀ tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Iniasi tí ó ti wà ní ìdùbúlẹ̀ àìsàn fún ọdún mẹjọ; kò lè dá ara gbé nílẹ̀.

34 Peteru bá sọ fún un pé, “Iniasi, Jesu Kristi wò ọ́ sàn. Dìde, kà ẹní rẹ.” Lẹsẹkẹsẹ, ó bá dìde.

35 Gbogbo àwọn tí ó ń gbé Lida ati Ṣaroni rí i, wọ́n bá yipada, wọ́n di onigbagbọ.

Peteru Jí Dọkasi Dìde

36 Ọmọ-ẹ̀yìn kan wà ní Jọpa, tí ó jẹ́ obinrin, orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Tabita, tabi Dọkasi ní èdè Giriki. (Ìtumọ̀ rẹ̀ ni èkùlù.) Obinrin yìí jẹ́ ẹnìkan tíí máa ṣe ọpọlọpọ iṣẹ́ rere, ó sì láàánú pupọ.

37 Ní àkókò yìí ó wá ṣàìsàn, ó sì kú. Wọ́n bá wẹ̀ ẹ́, wọ́n tẹ́ ẹ sí yàrá lókè ní ilé pẹ̀tẹ́ẹ̀sì kan.

38 Lida kò jìnnà sí Jọpa, nítorí náà àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu ní Jọpa ti gbọ́ pé Peteru wà ní Lida. Wọ́n bá rán ọkunrin meji lọ sibẹ, kí wọ́n lọ bẹ̀ ẹ́ pé kí ó má jáfara kí ó yára wá sọ́dọ̀ wọn.

39 Peteru bá gbéra, ó tẹ̀lé wọn. Nígbà tí ó dé Jọpa, ó lọ sí iyàrá lókè. Gbogbo àwọn opó bá yí i ká, wọ́n ń sunkún, wọ́n ń fi àwọn ẹ̀wù ati aṣọ tí Dọkasi máa ń rán fún wọn nígbà tí ó wà láàyè han Peteru.

40 Peteru bá ti gbogbo wọn jáde, ó kúnlẹ̀, ó gbadura. Ó bá kọjú sí òkú náà, ó ní, “Tabita, dìde.” Ni Tabita bá lajú, ó rí Peteru, ó bá dìde jókòó.

41 Peteru bá fà á lọ́wọ́ dìde. Ó pe àwọn eniyan Ọlọrun ati àwọn opó, ó bá fa Dọkasi lé wọn lọ́wọ́ láàyè.

42 Ìròyìn yìí tàn ká gbogbo Jọpa, ọpọlọpọ sì gba Oluwa gbọ́.

43 Peteru dúró fún ọjọ́ pupọ ní Jọpa, ní ọ̀dọ̀ Simoni, tí ń ṣe òwò awọ.