Categories
DIUTARONOMI

DIUTARONOMI 30

Ìpadà-bọ̀-sípò ati Ibukun Israẹli

1 “Nígbà tí gbogbo àwọn ibukun tabi ègún tí mo gbé kalẹ̀ níwájú yín lónìí bá ṣẹ mọ́ yín lára, tí ẹ bá dé ààrin àwọn orílẹ̀-èdè tí OLUWA yóo fọn yín ká sí, tí ẹ bá ranti anfaani tí ẹ ti sọnù,

2 tí ẹ bá yipada sí OLUWA Ọlọrun yín, ẹ̀yin ati àwọn ọmọ yín; tí ẹ bá tún ń gbọ́ tirẹ̀, tí ẹ sì ń fi tọkàntọkàn tẹ̀lé gbogbo òfin tí mo ṣe fun yín lónìí,

3 OLUWA Ọlọrun yín yóo dá ibukun yín pada, yóo ṣàánú yín, yóo sì tún ko yín pada láti ààrin àwọn orílẹ̀-èdè gbogbo tí ó fọn yín ká sí.

4 Ibi yòówù tí OLUWA bá fọn yín ká sí ninu ayé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ òpin ayé, OLUWA yóo wa yín rí, yóo sì ko yín jọ.

5 OLUWA Ọlọrun yín yóo tún da yín pada sí ilẹ̀ àwọn baba yín, ilẹ̀ náà yóo tún pada di tiyín, OLUWA yóo mú kí ó dára fun yín, yóo mú kí ẹ pọ̀ ju àwọn baba yín lọ.

6 OLUWA Ọlọrun yín yóo fún ẹ̀yin ati àwọn ọmọ yín ní ẹ̀mí ìgbọràn tí ó fi jẹ́ pé ẹ óo fẹ́ràn rẹ̀ tọkàntọkàn, ẹ óo sì wà láàyè.

7 OLUWA Ọlọrun yín yóo da àwọn ègún wọnyi sórí àwọn ọ̀tá yín tí wọ́n ṣe inúnibíni si yín.

8 Ẹ óo tún máa gbọ́ ti OLUWA, ẹ óo sì máa pa àwọn òfin rẹ̀ tí mò ń fun yín lónìí mọ́.

9 OLUWA Ọlọrun yín yóo bukun iṣẹ́ ọwọ́ yín lọpọlọpọ, ati àwọn ọmọ yín; àwọn ọmọ mààlúù yín, ati àwọn ohun ọ̀gbìn yín, nítorí inú OLUWA yóo tún dùn láti bukun yín gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe inú dídùn sí àwọn baba yín,

10 bí ẹ bá gbọ́ ti OLUWA Ọlọrun yín, tí ẹ pa àwọn òfin ati ìlànà rẹ̀ mọ́ bí a ti kọ ọ́ sinu ìwé òfin yìí, tí ẹ bá sì yipada tọkàntọkàn.

11 “Nítorí pé òfin tí mo fun yín lónìí kò le jù fun yín, kì í sìí ṣe ohun tí apá yín kò ká.

12 Kì í ṣe òkè ọ̀run ni ó wà, tí ẹ óo fi wí pé, ‘Ta ni yóo gun òkè ọ̀run lọ, tí yóo lọ bá wa mú un sọ̀kalẹ̀ wá, kí á lè gbọ́ kí á sì pa á mọ́?’

13 Bẹ́ẹ̀ ni kò sí ní òdìkejì òkun tí ẹ óo fi wí pé, ‘Ta ni yóo la òkun kọjá fún wa, tí yóo lọ bá wa mú un wá kí á lè gbọ́ kí á sì pa á mọ́?’

14 Ṣugbọn nítòsí yín ni ọ̀rọ̀ náà wà, ó wà lẹ́nu yín, ó sì wà ninu ọkàn yín, tí ó fi jẹ́ pé ẹ lè ṣe é.

15 “Wò ó, mo gbé ikú ati ìyè kalẹ̀ níwájú yín lónìí, bákan náà ni mo sì gbé ire ati ibi kalẹ̀.

16 Tí ẹ bá pa òfin OLUWA Ọlọrun yín mọ́ bí mo ti fun yín lónìí, tí ẹ̀ fẹ́ràn rẹ̀, tí ẹ̀ ń rìn ní ọ̀nà rẹ̀, tí ẹ sì ń pa àwọn òfin, ìlànà ati ìdájọ́ rẹ̀ mọ́, ẹ óo wà láàyè, ẹ óo sì máa pọ̀ sí i. OLUWA Ọlọrun yín yóo bukun yín ní ilẹ̀ tí ẹ̀ ń lọ gbà tí yóo sì di tiyín.

17 Ṣugbọn bí ọkàn yín bá yipada, tí ẹ kọ̀, tí ẹ kò gbọ́ tirẹ̀, tí ẹ bá jẹ́ kí wọn fà yín lọ bọ àwọn oriṣa, tí ẹ sì ń sìn wọ́n,

18 mo wí fun yín gbangba lónìí pé, ẹ óo parun. Ẹ kò ní pẹ́ rárá lórí ilẹ̀ tí ẹ̀ ń gòkè Jọdani lọ gbà, tí yóo sì di tiyín.

19 Mo fi ilẹ̀ ati ọ̀run ṣe ẹlẹ́rìí níwájú yín lónìí, pé mo fun yín ní anfaani láti yan ikú tabi ìyè, ati láti yan ibukun tabi ègún. Nítorí náà, ẹ yan ìyè kí ẹ̀yin ati àwọn ọmọ yín lè wà láàyè.

20 Ẹ fẹ́ràn OLUWA Ọlọrun yín, ẹ máa gbọ́ tirẹ̀, kí ẹ sì máa súnmọ́ ọn pẹ́kípẹ́kí, kí ẹ lè wà láàyè, kí ẹ lè pẹ́ láyé, kí ẹ sì lè máa gbé orí ilẹ̀ tí OLUWA búra láti fún àwọn baba yín, àní Abrahamu, Isaaki, ati Jakọbu.”

Categories
DIUTARONOMI

DIUTARONOMI 31

Joṣua Gba Ipò Mose

1 Mose tún bẹ̀rẹ̀ sí bá àwọn ọmọ Israẹli sọ̀rọ̀.

2 Ó ní, “Òní ni mo di ẹni ọgọfa ọdún (120), kò ní ṣeéṣe fún mi mọ́, láti máa fò síhìn-ín sọ́hùn-ún. OLUWA ti wí fún mi pé, n kò ní gun òkè odò Jọdani yìí.

3 OLUWA Ọlọrun yín tìkalára rẹ̀ ni yóo ṣiwaju yín lọ, yóo ba yín pa gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè náà run, tí ẹ ó fi lè gba ilẹ̀ wọn. Joṣua ni yóo sì jẹ́ olórí, tí yóo máa ṣiwaju yín lọ, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti wí.

4 Bí OLUWA ti ṣe sí Sihoni ati Ogu, ọba àwọn ará Amori, tí ó pa wọ́n run tàwọn ti ilẹ̀ wọn, bẹ́ẹ̀ ni yóo ṣe sí àwọn orílẹ̀-èdè yìí.

5 OLUWA yóo fi wọ́n lé yín lọ́wọ́, ẹ óo sì ṣe wọ́n bí mo ti pa á láṣẹ fun yín ninu òfin tí mo fun yín.

6 Ẹ múra gírí, kí ẹ sì mú ọkàn gidigidi. Ẹ má bẹ̀rù rárá, ẹ má sì ṣe jẹ́ kí àyà fò yín; nítorí pé, OLUWA Ọlọrun yín ń ba yín lọ. Kò ní já yín kulẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò ní fi yín sílẹ̀.”

7 Mose bá pe Joṣua, ó sọ fún un níwájú gbogbo àwọn eniyan Israẹli, pé, “Múra gírí, kí o sì mú ọkàn gidigidi nítorí ìwọ ni o óo kó àwọn eniyan wọnyi lọ sí ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun ti búra fún àwọn baba wọn pé òun yóo fi fún wọn. Ìwọ ni o óo sì fi lé wọn lọ́wọ́.

8 OLUWA Ọlọrun tìkalárarẹ̀ ni yóo máa ṣiwaju rẹ lọ, yóo sì máa wà pẹlu rẹ. Kò ní já ọ kulẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò ní fi ọ́ sílẹ̀. Má ṣe bẹ̀rù, má sì jẹ́ kí àyà fò ọ́.”

Kíka Òfin ní Ọdún Keje-keje

9 Mose bá kọ òfin yìí sílẹ̀, ó fún àwọn alufaa, àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n ru àpótí majẹmu OLUWA ati gbogbo àwọn àgbààgbà Israẹli.

10 Mose bá pàṣẹ fún wọn pé, “Ní ìparí ọdún keje-keje, ní àkókò tí a yà sọ́tọ̀ fún ọdún ìdásílẹ̀, ní àkókò àjọ̀dún àgọ́,

11 nígbà tí gbogbo àwọn ọmọ Israẹli bá wá sin OLUWA ní ibi tí ó yàn pé kí wọ́n ti máa sin òun, o gbọdọ̀ máa ka òfin yìí sí etígbọ̀ọ́ gbogbo wọn.

12 Pe àwọn eniyan náà jọ, ati ọkunrin ati obinrin, ati ọmọde ati àgbà, ati onílé ati àlejò, tí ó wà ninu ìlú yín, kí wọ́n lè gbọ́, kí wọ́n sì kọ́ láti bẹ̀rù OLUWA Ọlọrun yín, kí wọ́n sì máa fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ tẹ̀lé gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ tí ó wà ninu òfin yìí.

13 Kí àwọn ọmọ wọn tí kò tíì mọ̀ ọ́n lè gbọ́ nípa rẹ̀, kí wọ́n sì lè kọ́ láti bẹ̀rù OLUWA Ọlọrun yín, níwọ̀n ìgbà tí ẹ bá wà lórí ilẹ̀ tí ẹ̀ ń rékọjá lọ sí òkè odò Jọdani láti gbà.”

Ìlànà Ìkẹyìn Tí OLUWA fún Mose

14 OLUWA Ọlọrun sọ fún Mose pé, “Àkókò ń tó bọ̀ tí o óo kú, pe Joṣua, kí ẹ̀yin mejeeji wá sinu àgọ́ àjọ kí n lè fi ohun tí yóo ṣe lé e lọ́wọ́.” Mose ati Joṣua bá wọ inú àgọ́ àjọ lọ.

15 OLUWA fi ara hàn wọ́n ninu ọ̀wọ̀n ìkùukùu ninu àgọ́ náà. Ọ̀wọ̀n ìkùukùu náà wà ní ẹ̀bá ẹnu ọ̀nà àgọ́.

16 OLUWA tún sọ fún Mose pé, “Ọjọ́ àtisùn rẹ kù sí dẹ̀dẹ̀. Àwọn eniyan wọnyi yóo lọ máa bọ àwọn oriṣa tí àwọn ará ilẹ̀ náà ń bọ. Wọn óo kọ̀ mí sílẹ̀, wọn óo sì da majẹmu tí mo bá wọn dá.

17 Inú mi yóo ru sí wọn ní ọjọ́ náà, èmi náà óo kọ̀ wọ́n sílẹ̀, n óo mú ojú mi kúrò lára wọn, n óo sì pa wọ́n run. Oríṣìíríṣìí ibi ati wahala ni yóo bá wọn, tóbẹ́ẹ̀ tí wọn yóo máa wí ní ọjọ́ náà pé, ‘Ǹjẹ́ nítorí pé kò sí Ọlọrun wa láàrin wa kọ́ ni gbogbo ibi wọnyi fi dé bá wa?’

18 Láìṣe àní àní, n óo mú ojú kúrò lára wọn ní ọjọ́ náà, nítorí gbogbo ibi tí wọ́n ti ṣe, nítorí pé wọ́n ti yipada, wọ́n sì ń bọ oriṣa.

19 “Nítorí náà, kọ orin yìí sílẹ̀ nisinsinyii kí o sì kọ́ àwọn ọmọ Israẹli, kí orin náà lè jẹ́ ẹlẹ́rìí mi lọ́dọ̀ wọn.

20 Nítorí pé, nígbà tí mo bá kó wọn wọ ilẹ̀ tí ó kún fún wàrà ati oyin, tí mo ti búra pé n óo fún àwọn baba wọn; nígbà tí wọ́n bá jẹ, tí wọ́n yó tán, tí wọ́n sì sanra, wọn óo yipada sọ́dọ̀ àwọn oriṣa, wọn óo sì máa bọ wọ́n. Wọn óo kọ̀ mí sílẹ̀, wọn óo sì da majẹmu mi.

21 Nígbà tí ọpọlọpọ ibi ati wahala bá dé bá wọn, orin yìí ni yóo jẹ́ ẹ̀rí fún wọn (nítorí pé arọmọdọmọ wọn yóo máa kọ ọ́, wọn kò sì ní gbàgbé rẹ̀); nítorí pé mo mọ ète tí wọn ń pa, kí ó tilẹ̀ tó di pé mo mú wọn wọ ilẹ̀ tí mo búra láti fún wọn.”

22 Mose bá kọ orin yìí ní ọjọ́ náà-gan an, ó sì kọ́ àwọn ọmọ Israẹli.

23 OLUWA fi iṣẹ́ lé Joṣua ọmọ Nuni lọ́wọ́, ó ní, “Múra gírí kí o sì mú ọkàn gidigidi, nítorí ìwọ ni o óo kó àwọn ọmọ Israẹli wọ ilẹ̀ tí mo ti búra láti fún wọn. N óo wà pẹlu rẹ.”

24 Nígbà tí Mose kọ gbogbo ohun tí ó wà ninu ìwé òfin yìí tán patapata,

25 ó pàṣẹ fún àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n ru àpótí majẹmu OLUWA,

26 ó ní, “Ẹ fi ìwé òfin yìí sí ẹ̀gbẹ́ àpótí majẹmu OLUWA Ọlọrun yín, kí ó wà níbẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí pẹlu yín;

27 nítorí mo mọ̀ pé ọlọ̀tẹ̀ ati olóríkunkun ni yín; nígbà tí mo wà láàyè pẹlu yín lónìí, ẹ̀ ń ṣọ̀tẹ̀ sí OLUWA, kí á má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ ìgbà tí mo bá kú tán.

28 Ẹ pe gbogbo àwọn àgbààgbà ẹ̀yà yín wá sọ́dọ̀ mi, ati gbogbo àwọn olórí ninu yín, kí àwọn náà lè máa gbọ́ bí mo ti ń sọ ọ̀rọ̀ yìí, kí ẹ sì pe ọ̀run ati ayé láti ṣe ẹlẹ́rìí wọn.

29 Nítorí mo mọ̀ dájú pé gẹ́rẹ́ tí mo bá kú tán, ìṣekúṣe ni ẹ óo máa ṣe, ẹ óo sì yipada kúrò ní ọ̀nà tí mo ti pa láṣẹ fun yín, ibi ni yóo sì ba yín ní ọjọ́ iwájú, nítorí pé ẹ óo ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA. Iṣẹ́ ọwọ́ yín yóo sì mú un bínú.”

Orin Mose

30 Mose ka gbogbo ọ̀rọ̀ orin náà patapata sí etígbọ̀ọ́ àpéjọ àwọn ọmọ Israẹli.

Categories
DIUTARONOMI

DIUTARONOMI 32

1 Ó ní:

“Tẹ́tísílẹ̀, ìwọ ọ̀run, mo fẹ́ sọ̀rọ̀;

gbọ́ ohun tí mo fẹ́ sọ, ìwọ ayé.

2 Kí ẹ̀kọ́ mi kí ó máa rọ̀ bí òjò,

àní, bí ọ̀wààrà òjò tíí dẹ ewébẹ̀ lọ́rùn;

kí ó sì máa sẹ̀ bí ìrì,

bí òjò wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́ tíí tu koríko lára.

3 Nítorí pé n óo polongo orúkọ OLUWA,

àwọn eniyan rẹ yóo sì sọ nípa títóbi rẹ̀.

4 “Pípé ni iṣẹ́ ọwọ́ OLUWA, àpáta ààbò yín,

gbogbo ọ̀nà rẹ̀ sì jẹ́ ẹ̀tọ́.

Olódodo ni Ọlọrun, ẹni tí kì í ṣe àṣìṣe,

ẹ̀tọ́ ní í máa ń ṣe nígbà gbogbo.

5 Ṣugbọn ẹ̀yin ọmọ Israẹli ti hu ìwà aiṣododo sí i,

ẹ kò sì yẹ ní ẹni tí à bá máa pè ní ọmọ rẹ̀ mọ́,

nítorí àbùkù yín;

ẹ̀yin ìran ọlọ̀tẹ̀ ati ẹlẹ́ṣẹ̀ yìí.

6 Ṣé irú ohun tí ó yẹ kí ẹ fi san án fún OLUWA nìyí,

ẹ̀yin ìran òmùgọ̀ ati aláìnírònú ẹ̀dá wọnyi?

Ṣebí òun ni baba yín, tí ó da yín,

Tí ó da yín tán, tí ó sì fi ìdí yín múlẹ̀.

7 “Ẹ ranti ìgbà àtijọ́,

ẹ ṣe akiyesi ọpọlọpọ ọdún tí ó ti kọjá.

Ẹ bèèrè lọ́wọ́ baba yín, yóo fihàn yín,

Ẹ bi àwọn àgbààgbà yín,

wọn yóo sì sọ fun yín.

8 Nígbà tí Ọlọrun ọ̀gá ògo pín ilẹ̀ ìní fún àwọn orílẹ̀-èdè,

ó ṣètò ibi tí orílẹ̀-èdè kọ̀ọ̀kan yóo máa gbé,

gẹ́gẹ́ bí ìdílé kọ̀ọ̀kan láàrin àwọn ọmọ Israẹli.

9 Nítorí pé ìpín OLUWA ni àwọn eniyan rẹ̀,

ó yan àwọn ọmọ Jakọbu ní ohun ìní fún ara rẹ̀.

10 “Ninu aṣálẹ̀ ni ó ti rí wọn,

níbi tí kò sí igi tabi koríko, àfi kìkì yanrìn.

Ó yí wọn ká, ó sì ń tọ́jú wọn,

Ó sì dáàbò bò wọ́n bí ẹyin ojú rẹ̀.

11 Bí ẹyẹ idì tií tú ìtẹ́ rẹ̀ ká,

láti kọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ bí à á tíí fò,

tíí sì í na apá rẹ̀ láti hán wọn

tí wọ́n bá fẹ́ já bọ́,

bẹ́ẹ̀ ni OLUWA ń ṣe sí Israẹli.

12 OLUWA nìkan ṣoṣo ni ó ṣáájú àwọn eniyan rẹ̀,

láìsí ìrànlọ́wọ́ oriṣa kankan.

13 “Ó fi wọ́n jọba lórí àwọn òkè ayé,

ó sì fún wọn ní èso ilẹ̀ jẹ.

Ó pèsè oyin fún wọn láti inú àpáta,

ó sì mú kí igi olifi hù fún wọn lórí ilẹ̀ olókùúta.

14 Wọn rí ọpọlọpọ wàrà lára mààlúù wọn,

ati ọ̀pọ̀ omi wàrà lára ewúrẹ́ wọn,

ó fún wọn ní ọ̀rá ọ̀dọ́ aguntan ati ti àgbò,

ó fún wọn ní mààlúù Baṣani, ati ewúrẹ́,

ati ọkà tí ó dára jùlọ,

ati ọpọlọpọ ọtí waini.

15 “Ṣugbọn ẹ̀yin ọmọ Jeṣuruni, ẹ yó tán,

ẹ wá tàpá sí àṣẹ;

ẹ rí jẹ, ẹ rí mu, ẹ sì lókun lára;

ẹ wá gbàgbé Ọlọrun tí ó da yín,

ẹ sì ń pẹ̀gàn àpáta ìgbàlà yín!

16 Wọ́n fi ìbọ̀rìṣà wọn sọ OLUWA di òjòwú;

wọ́n fi ìwà burúkú wọn mú kí ibinu OLUWA wọn ru sókè.

17 Wọ́n tún bẹ̀rẹ̀ sí rúbọ sí àwọn ẹ̀mí burúkú,

Àwọn oriṣa tí wọn kò mọ̀ rí,

tí àwọn baba wọn kò sì bọ rí.

18 Ẹ gbàgbé àpáta ìgbàlà yín,

ẹ gbàgbé Ọlọrun tí ó da yín.

19 “Nígbà tí OLUWA rí ohun tí àwọn ọmọ rẹ̀ ń ṣe,

ó kọ̀ wọ́n sílẹ̀,

nítorí pé, wọ́n mú un bínú.

20 Ó ní, ‘N óo mójú kúrò lára wọn,

n óo sì máa wò bí ìgbẹ̀yìn wọn yóo ti rí.

Nítorí olóríkunkun ni wọ́n,

àwọn alaiṣootọ ọmọ!

21 Nítorí oriṣa lásánlàsàn,

wọn sọ èmi Ọlọrun di òjòwú;

wọn sì ti fi àwọn ère wọn mú mi bínú.

Nítorí náà, èmi náà óo lo àwọn eniyan lásánlàsàn

láti mu àwọn náà jowú,

n óo sì lo aṣiwèrè orílẹ̀-èdè lásánlàsàn kan

láti mú wọn bínú.

22 Nítorí iná ibinu mi ń jó,

yóo sì jó títí dé isà òkú.

Yóo jó ayé ati ohun gbogbo tí ń bẹ ninu rẹ̀ ní àjórun,

tó fi mọ́ ìpìlẹ̀ àwọn òkè ńlá.

23 “ ‘N óo da oríṣìíríṣìí ibi sórí wọn,

n óo sì rọ òjò ọfà mi sára wọn.

24 N óo fi ebi pa wọ́n ní àpakú,

iná yóo jó wọn ní àjórun,

n óo sì fi àjàkálẹ̀ àrùn pa wọ́n run.

N óo jẹ́ kí àwọn ẹranko burúkú pa wọ́n jẹ,

n óo sì jẹ́ kí àwọn ejò olóró bù wọ́n ṣán.

25 Bí idà tí ń pa àwọn kan lójú pópó,

bẹ́ẹ̀ ni ikú yóo di ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ láàrin ọ̀dẹ̀dẹ̀.

Bó ti ń pa àwọn ọdọmọkunrin, bẹ́ẹ̀ ni yóo máa pa àwọn ọdọmọbinrin,

ati àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ ati àwọn arúgbó kùjọ́kùjọ́,

gbogbo wọn ni ikú gbígbóná yóo máa mú lọ.

26 Ǹ bá wí pé kí n fọ́n wọn káàkiri,

kí ẹnikẹ́ni má tilẹ̀ ranti wọn mọ́,

27 ti àwọn ọ̀tá wọn ni mo rò,

nítorí pé, ọ̀tọ̀ ni ohun tí wọn yóo máa wí kiri.

Wọn yóo máa wí pé,

“Àwa ni a ṣẹgun wọn,

kìí ṣe OLUWA ló ṣe é rárá.” ’

28 “Nítorí pé aláìlérò orílẹ̀-èdè ni Israẹli,

òye kò sì yé wọn rárá.

29 Bí ó bá ṣe pé wọ́n gbọ́n ni,

tí òye sì yé wọn;

wọn ì bá ti mọ̀ bí ìgbẹ̀yìn wọn yóo ti rí.

30 Ẹyọ ẹnìkan ṣoṣo ṣe lè lé ẹgbẹrun eniyan?

Àní, eniyan meji péré ṣe lè lé ẹgbaarun eniyan sá?

Bí kò bá jẹ́ pé Ọlọrun aláàbò wọn ti kọ̀ wọ́n sílẹ̀,

tí OLUWA sì ti fi wọ́n lé àwọn ọ̀tá wọn lọ́wọ́.

31 Nítorí pé, àwọn ọ̀tá wọn pàápàá mọ̀ pé,

Ọlọrun, aláàbò Israẹli, kì í ṣe ẹgbẹ́ àwọn oriṣa wọn.

32 Àwọn ọ̀tá wọn ti bàjẹ́ bíi Sodomu ati Gomora,

wọ́n dàbí àjàrà tí ń so èso tí ó korò tí ó sì lóró.

33 Oró ejò ni ọtí wọn,

àní oró paramọ́lẹ̀ tíí ṣe ikú pani.

34 “Èmi OLUWA kò gbàgbé ohun tí àwọn ọ̀tá wọn ṣe,

ṣebí gbogbo rẹ̀ wà ní àkọsílẹ̀ lọ́dọ̀ mi?

35 Èmi OLUWA ni ẹlẹ́san, n óo sì gbẹ̀san,

nítorí ọjọ́ ń bọ̀, tí àwọn pàápàá yóo yọ̀ ṣubú.

Ọjọ́ ìdààmú wọn kù sí dẹ̀dẹ̀,

ọjọ́ ìparun wọn sì ń bọ̀ kíákíá.

36 Nítorí pé, OLUWA yóo dá àwọn eniyan rẹ̀ láre,

yóo sì ṣàánú fún àwọn iranṣẹ rẹ̀,

nígbà tí ó bá rí i pé wọn kò lágbára mọ́,

ati pé kò sí olùrànlọ́wọ́ fún wọn,

tí kò sì ṣẹ́ku ẹnìkan ninu wọn,

kì báà ṣe ẹrú tabi òmìnira.

37 Nígbà náà ni yóo bi wọ́n pé,

‘Níbo ni àwọn oriṣa yin wà,

ati àpáta tí ẹ fi ṣe ààbò yin?

38 Ṣebí àwọn ni ẹ fún ní ọ̀rá ẹran ìrúbọ yín,

àwọn ni ẹ sì rú ẹbọ ohun mímu yín sí?

Kí wọ́n dìde, kí wọ́n ràn yín lọ́wọ́ nisinsinyii,

kí wọ́n sì dáàbò bò yín.

39 “ ‘Ṣé ẹ wá rí i nisinsinyii pé,

èmi nìkan ṣoṣo ni Ọlọrun,

kò sí ọlọrun mìíràn mọ, lẹ́yìn mi.

Mo lè pa eniyan,

mo sì lè sọ ọ́ di ààyè.

Mo lè ṣá eniyan lọ́gbẹ́,

mo sì lè wò ó sàn.

Bí mo bá gbá eniyan mú,

kò sí ẹni tí ó lè gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ mi.

40 Níwọ̀n bí mo ṣe jẹ́ Ọlọrun alààyè,

mo fi ara mi búra.

41 Nígbà tí mo bá pọ́n idà mi,

tí ó ń kọ yànrànyànràn,

n óo fà á yọ láti fi ṣe ẹ̀tọ́.

N óo gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá mi,

n óo sì jẹ àwọn tí wọ́n kórìíra mi níyà.

42 Ọfà mi yóo tẹnu bọ ẹ̀jẹ̀,

yóo sì mu àmuyó.

Idà mi yóo sì bẹ́ gbogbo àwọn tí wọ́n lòdì sí mi.

N kò ni dá ẹnikẹ́ni sí, ninu àwọn tí wọ́n gbógun tì mí,

ati àwọn tí wọ́n ti fara gbọgbẹ́,

ati àwọn tí wọ́n dì nígbèkùn,

gbogbo wọn ni n óo pa.’

43 “Ẹ máa yìn ín ẹ̀yin eniyan OLUWA,

gbogbo ẹ̀yin orílẹ̀-èdè,

nítorí pé yóo gbẹ̀san lára àwọn tí wọ́n bá pa àwọn iranṣẹ rẹ̀.

Yóo sì jẹ àwọn ọ̀tá rẹ̀ níyà,

yóo sì ṣe ètùtù fún ilẹ̀ àwọn eniyan rẹ̀.”

44 Mose wá, ó sì ka gbogbo ọ̀rọ̀ orin yìí sí etígbọ̀ọ́ àwọn eniyan náà, òun ati Joṣua ọmọ Nuni.

Ìlànà Ìkẹyìn tí Mose fún Wọn

45 Nígbà tí Mose bá àwọn ọmọ Israẹli sọ gbogbo ọ̀rọ̀ wọnyi tán,

46 ó ní, “Ẹ fi gbogbo ọ̀rọ̀ tí mo ba yín sọ lónìí sọ́kàn, kí ẹ sì pa á láṣẹ fún àwọn ọmọ yín, kí wọ́n lè pa gbogbo òfin wọnyi mọ́ lẹ́sẹẹsẹ.

47 Nítorí pé kìí ṣe nǹkan yẹpẹrẹ ni, òun ni ẹ̀mí yín. Bí ẹ bá pa á mọ́, ẹ óo wà láàyè, ẹ óo sì pẹ́ lórí ilẹ̀ tí ẹ̀ ń rékọjá Jọdani lọ gbà.”

48 OLUWA sọ fún Mose ní ọjọ́ náà gan-an pé,

49 “Lọ sí òkè Abarimu tí ó dojú kọ ìlú Jẹriko, ní ilẹ̀ Moabu. Gun orí òkè Nebo lọ, kí o sì wo gbogbo ilẹ̀ Kenaani tí mo fún àwọn eniyan Israẹli.

50 Orí òkè Nebo yìí ni o óo kú sí, bí Aaroni arakunrin rẹ ṣe kú lórí òkè Hori.

51 Nítorí pé, ẹ̀yin mejeeji ni ẹ kò hùwà òtítọ́ sí mi láàrin àwọn ọmọ Israẹli, nígbà tí ẹ wà ní odò Meriba Kadeṣi, ní aṣálẹ̀ Sini. Ẹ tàbùkù mi lójú gbogbo àwọn eniyan, ẹ kò bọ̀wọ̀ fún mi gẹ́gẹ́ bí ẹni mímọ́ níwájú àwọn eniyan náà.

52 Nítorí náà, o óo fi ojú rí ilẹ̀ náà, ṣugbọn ẹsẹ̀ rẹ kò ní tẹ ilẹ̀ tí n ó fún àwọn eniyan Israẹli.”

Categories
DIUTARONOMI

DIUTARONOMI 33

Mose Súre fún Àwọn Ẹ̀yà Israẹli

1 Ìre tí Mose eniyan Ọlọrun sú fún àwọn ọmọ Israẹli kí ó tó kú nìyí. Ó ní:

2 OLUWA wá láti orí òkè Sinai,

ó yọ gẹ́gẹ́ bí oòrùn láti Edomu,

ó ràn sórí àwọn eniyan rẹ̀ láti òkè Parani.

Ó wá láti ọ̀dọ̀ ẹgbaarun àwọn ẹni mímọ́,

ó gbé iná tí ń jò lọ́wọ́ ọ̀tún rẹ̀.

3 Ọlọrun fẹ́ràn àwọn eniyan rẹ̀,

gbogbo àwọn tí a yà sọ́tọ̀ fún un wà lọ́wọ́ rẹ̀,

nítorí náà ni wọ́n ṣe ń tẹ̀lé ọ̀nà rẹ̀,

tí wọ́n sì ń gba àṣẹ lọ́dọ̀ rẹ̀,

4 nígbà tí Mose bá fún wa ní òfin,

tí ó jẹ́ ohun ìní gbogbo eniyan Israẹli.

5 Bẹ́ẹ̀ ni OLUWA ṣe di ọba ní Jeṣuruni,

nígbà tí gbogbo àwọn olórí péjọ,

àní, gbogbo àwọn olórí ninu ẹ̀yà Israẹli.

6 Mose súre fún ẹ̀yà Reubẹni, ó ní:

“Ẹ̀yà Reubẹni yóo máa wà ni, kò ní parun,

àwọn eniyan rẹ̀ kò ní dínkù.”

7 Ó súre fún ẹ̀yà Juda pé:

“OLUWA, gbọ́ igbe ẹ̀yà Juda,

nígbà tí wọ́n bá pè fún ìrànwọ́,

sì kó wọn pada sọ́dọ̀ àwọn eniyan wọn.

Fi ọwọ́ ara rẹ jà fún wọn,

sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti borí àwọn ọ̀tá wọn.”

8 Ó súre fún ẹ̀yà Lefi pé:

“OLUWA, fún Lefi, ẹni tíí ṣe olódodo, ní Tumimu ati Urimu rẹ;

Lefi, tí o dánwò ní Masa,

tí o sì bá jà níbi odò tí ó wà ní Meriba;

9 àwọn tí wọ́n sọ pé àwọn kò ka òbí àwọn sí, ju ìwọ OLUWA lọ;

wọ́n kọ àwọn arakunrin wọn sílẹ̀,

wọ́n sì ṣá àwọn ọmọ wọn tì.

Nítorí pé wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ,

wọ́n sì ń pa majẹmu rẹ mọ́.

10 Wọn óo kọ́ ilé Jakọbu ní ìlànà rẹ,

wọn óo sì kọ́ àwọn ọmọ Israẹli ní òfin rẹ.

Àwọn ni wọn óo máa sun turari níbi ẹbọ rẹ,

wọn óo sì máa rú ẹbọ sísun lórí pẹpẹ rẹ.

11 OLUWA, bukun àwọn ohun ìní wọn,

sì jẹ́ kí iṣẹ́ ọwọ́ wọn jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà lójú rẹ,

Fọ́ egungun itan àwọn ọ̀tá wọn,

tẹ̀ wọ́n ní àtẹ̀rẹ́,

kí àwọn tí wọ́n bá kórìíra wọn má sì lè gbérí mọ́.”

12 Ó súre fún ẹ̀yà Bẹnjamini pé:

“Bẹnjamini, ẹ̀yà tí OLUWA fẹ́ràn tí ó sì ń dáàbò bò,

OLUWA ń ṣọ́ wọn nígbà gbogbo,

ó sì ń gbé ààrin wọn.”

13 Ó súre fún ẹ̀yà Josẹfu pé:

“Kí OLUWA rọ òjò ibukun sórí ilẹ̀ wọn,

kí ó sì bu omi rin ín láti abẹ́ ilẹ̀ wá.

14 Kí OLUWA pèsè ọpọlọpọ èso sórí ilẹ̀ wọn,

kí ó sì kún fún àwọn èso tí ó dára jùlọ láti ìgbà dé ìgbà.

15 Kí àwọn òkè ńláńlá àtijọ́ so ọpọlọpọ èso dáradára,

kí ọpọlọpọ èso sì bo àwọn òkè kéékèèké.

16 Kí ilẹ̀ wọn kún fún oríṣìíríṣìí àwọn ohun tí ó dára,

pẹlu ibukun láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ń gbé inú pápá tí ń jó.

Kí ó wá sórí Josẹfu,

àní, sórí ẹni tó jẹ́ aṣiwaju fún àwọn arakunrin rẹ̀.

17 Àkọ́bí rẹ̀ lágbára bí akọ mààlúù,

Ìwo rẹ̀ sì dàbí ìwo mààlúù tí ó lágbára,

tí yóo fi máa ti àwọn orílẹ̀-èdè títí dé òpin ayé.

Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ẹgbẹẹgbaarun àwọn ọmọ Efuraimu,

ati ẹgbẹẹgbẹrun àwọn ọmọ Manase.”

18 Ó súre fún Sebuluni ati fún Isakari, ó ní:

“Máa yọ̀ bí o ti ń jáde lọ, ìwọ Sebuluni,

sì máa yọ̀ ninu ilé rẹ, ìwọ Isakari.

19 Wọn óo pe àwọn àlejò jọ sórí òkè,

wọn óo sì máa rú ẹbọ ní ọ̀nà ẹ̀tọ́ níbẹ̀.

Nítorí wọn óo máa kó ọrọ̀ jọ láti inú òkun,

ati dúkìá tí ó farasin láti inú yanrìn etí òkun.”

20 Ìre tí ó sú fún ẹ̀yà Gadi ni pé:

“Ibukun ni fún ẹni tí ó bukun ilẹ̀ Gadi,

Gadi dàbí kinniun tí ó ba láti fani lápá ya, ati láti géni lórí.

21 Ibi tí ó dára jùlọ ninu ilẹ̀ náà ni wọ́n mú fún ara wọn,

nítorí pé ibẹ̀ ni ìpín olórí ogun wà,

ó wá sí ọ̀dọ̀ àwọn olórí àwọn eniyan náà,

àtòun, àtàwọn eniyan náà sì ń pa àṣẹ OLUWA mọ́,

wọn sì ń ṣe ìdájọ́ òdodo.”

22 Ó súre fun ẹ̀yà Dani pé:

“Dani dàbí ẹgbọ̀rọ̀ kinniun, tí ó fò jáde láti Baṣani.”

23 Ó súre fún ẹ̀yà Nafutali pé:

“OLUWA ti ṣíjú rere wo Nafutali,

ó sì ti bukun un lọpọlọpọ,

ilẹ̀ wọn bẹ̀rẹ̀ láti adágún Galili,

títí lọ kan gúsù gbọ̀ngbọ̀n.”

24 Ìre tí ó sú fún ẹ̀yà Aṣeri ni pé:

“Ibukun ẹ̀yà Aṣeri ta gbogbo ibukun ẹ̀yà yòókù yọ,

àyànfẹ́ ni yóo jẹ́ láàrin àwọn arakunrin rẹ̀,

ilẹ̀ rẹ̀ yóo sì kún fún òróró olifi.

25 Ọ̀pá ìdábùú ìlẹ̀kùn rẹ̀ yóo jẹ́ irin ati idẹ,

bí iye ọjọ́ orí rẹ̀ bá ti tó, bẹ́ẹ̀ ni agbára rẹ̀ yóo pọ̀ tó.”

26 Ẹ̀yin ará Jeṣuruni,

kò sí ẹni tí ó dàbí Ọlọrun yín,

tí ó gun awọsanma lẹ́ṣin ninu ọlá ńlá rẹ̀,

láti wá ràn yín lọ́wọ́.

27 Ọlọrun ayérayé ni ààbò yín,

ọwọ́ rẹ̀ ni ó sì fi ń gbé yín ró.

Bí ẹ ti ń súnmọ́ wájú,

bẹ́ẹ̀ ni ó ń lé àwọn ọ̀tá yín jáde,

tí ó sì ní kí ẹ máa pa wọ́n run.

28 Nítorí náà, Israẹli wà ní alaafia,

àwọn ọmọ Jakọbu sì ń gbé láìléwu,

ní ilẹ̀ tí ó kún fún ọkà ati ọtí waini,

tí ìrì sì ń sẹ̀ sórí rẹ̀ láti ọ̀run wá.

29 Ẹ máa fò fún ayọ̀, ẹ̀yin ọmọ Israẹli,

ta ló tún dàbí yín,

ẹ̀yin orílẹ̀-èdè tí OLUWA tìkalárarẹ̀ gbàlà?

OLUWA tìkalárarẹ̀ ni ààbò yín, ati idà yín,

òun ní ń dáàbò bò yín, tí ó sì ń fun yín ní ìṣẹ́gun.

Àwọn ọ̀tá yín ni yóo máa wá bẹ̀bẹ̀ fún àánú,

ẹ óo sì máa tẹ àwọn pẹpẹ ìrúbọ wọn mọ́lẹ̀.

Categories
DIUTARONOMI

DIUTARONOMI 34

Ikú Mose

1 Mose gbéra láti pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu, ó gun orí òkè Nebo lọ títí dé ṣóńṣó òkè Pisiga, tí ó wà ní òdìkejì Jẹriko. OLUWA sì fi gbogbo ilẹ̀ náà hàn án láti Gileadi lọ, títí dé Dani,

2 gbogbo ilẹ̀ Nafutali, ilẹ̀ Efuraimu, ilẹ̀ Manase, ati gbogbo ilẹ̀ Juda, títí dé etí òkun ìwọ̀ oòrùn,

3 ilẹ̀ Nẹgẹbu ni apá gúsù ati gbogbo pẹ̀tẹ́lẹ̀ tí ó wà ní àfonífojì Jẹriko, ìlú tí ó kún fún ọ̀pẹ, títí dé ilẹ̀ Soari.

4 OLUWA wí fún un pé, “Ilẹ̀ tí mo búra fún Abrahamu, ati fún Isaaki, ati fún Jakọbu pé, n óo fi fún àwọn arọmọdọmọ wọn nìyí, mo jẹ́ kí o rí i, ṣugbọn o kò ní dé ibẹ̀.”

5 Mose iranṣẹ OLUWA kú ní ilẹ̀ Moabu gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ OLUWA.

6 OLUWA sin ín sí àfonífojì ilẹ̀ Moabu tí ó dojú kọ Betipeori, ṣugbọn ẹnikẹ́ni kò mọ ibojì rẹ̀ títí di òní olónìí.

7 Mose jẹ́ ẹni ọgọfa (120) ọdún nígbà tí ó kú, ojú rẹ̀ kò ṣe bàìbàì, bẹ́ẹ̀ ni agbára rẹ̀ kò dínkù.

8 Àwọn ọmọ Israẹli ṣọ̀fọ̀ Mose fún ọgbọ̀n ọjọ́ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu, wọ́n sì parí ṣíṣe òkú rẹ̀.

9 Joṣua ọmọ Nuni kún fún ọgbọ́n nítorí pé Mose ti gbé ọwọ́ rẹ̀ lé e, nítorí náà àwọn ọmọ Israẹli ń gbọ́ tirẹ̀, wọ́n sì ń ṣe gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí OLUWA pa fún Mose.

10 Láti ìgbà náà, kò tíì sí wolii mìíràn ní ilẹ̀ Israẹli tí ó dàbí Mose, ẹni tí Ọlọrun bá sọ̀rọ̀ lojukooju.

11 Kò sì sí ẹlòmíràn tí OLUWA rán láti ṣe ọpọlọpọ iṣẹ́ ìyanu lára Farao ati gbogbo àwọn iranṣẹ rẹ̀ ati gbogbo ilẹ̀ rẹ̀, ní ilẹ̀ Ijipti.

12 Bẹ́ẹ̀ ni kò sí wolii mìíràn tí ó ní agbára ńlá tabi tí ó ṣe àwọn ohun tí ó bani lẹ́rù bí Mose ti ṣe lójú gbogbo àwọn ọmọ Israẹli.