Categories
ÀWỌN ỌBA KINNI

ÀWỌN ỌBA KINNI 20

Israẹli bá Siria Jagun

1 Benhadadi, ọba Siria kó gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jọ; àwọn ọba mejilelọgbọn ni wọ́n wá láti ràn án lọ́wọ́, pẹlu gbogbo ẹṣin, ati gbogbo kẹ̀kẹ́ ogun wọn. Wọ́n dó ti ìlú Samaria, wọ́n sì bá a jagun.

2 Ó rán àwọn oníṣẹ́ sí ààrin ìlú pé kí wọ́n sọ fún Ahabu, ọba Israẹli pé, “Benhadadi ọba ní,

3 ‘Tèmi ni gbogbo fadaka ati wúrà rẹ, tèmi náà sì ni àwọn tí wọ́n dára jùlọ lára àwọn aya rẹ, ati àwọn ọmọ rẹ.’ ”

4 Ahabu ọba bá ranṣẹ pada pé, “Gẹ́gẹ́ bí o ti sọ, oluwa mi, ìwọ ni o ni mí ati gbogbo ohun tí mo ní.”

5 Àwọn oníṣẹ́ náà tún pada wá sí ọ̀dọ̀ Ahabu, wọ́n ní Benhadadi ọba tún ranṣẹ, ó ní, òun ti ranṣẹ sí Ahabu pé kí ó kó fadaka rẹ̀ ati wúrà rẹ̀, ati àwọn obinrin rẹ̀, ati àwọn ọmọ rẹ̀ fún òun,

6 ṣugbọn òun óo rán àwọn oníṣẹ́ òun sí i ní ìwòyí ọ̀la láti yẹ ààfin rẹ̀ wò ati ilé àwọn oníṣẹ́ rẹ̀, kí wọ́n sì kó ohunkohun tí ó bá wù wọ́n.

7 Nígbà náà ni Ahabu ọba ranṣẹ pe gbogbo àwọn àgbààgbà ilẹ̀ náà, ó wí fún wọn pé, “Ṣé ẹ rí i pé ọkunrin yìí ń wá ìjàngbọ̀n? Ó ranṣẹ wá pé kí n kó fadaka ati wúrà mi, ati àwọn obinrin mi, ati àwọn ọmọ mi fún òun, n kò sì bá a jiyàn.”

8 Àwọn àgbààgbà bá dá a lóhùn pé, “Má dá a lóhùn rárá, má sì gbà fún un.”

9 Ahabu bá ranṣẹ pada sí Benhadadi ọba pé, “Mo faramọ́ ohun tí ó kọ́kọ́ bèèrè fún, ṣugbọn n kò lè gba ti ẹẹkeji yìí.”

Àwọn oníṣẹ́ náà pada lọ jíṣẹ́ fún Benhadadi ọba.

10 Benhadadi ọba tún ranṣẹ pada pé, “Àwọn oriṣa ń gbọ́! Mò ń kó àwọn eniyan bọ̀ láti pa ìlú Samaria run, wọ́n pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tó fi jẹ́ pé ọwọ́ lásán ni wọn yóo fi kó gbogbo erùpẹ̀ ìlú náà. Bí kò bá rí bẹ́ẹ̀, kí àwọn oriṣa pa mí.”

11 Ahabu ọba ranṣẹ pada, ó ní, “Jagunjagun kan kì í fọ́nnu kí ó tó lọ sójú ogun, ó di ìgbà tí ó bá lọ sógun tí ó bá bọ̀.”

12 Nígbà tí Benhadadi gbọ́ iṣẹ́ yìí níbi tí ó ti ń mu ọtí pẹlu àwọn ọba yòókù ninu àgọ́, ó pàṣẹ fún àwọn eniyan rẹ̀ pé kí wọ́n lọ múra ogun. Wọ́n bá múra láti bá Samaria jagun.

13 Wolii kan bá tọ Ahabu ọba lọ, ó wí fún un pé, “OLUWA ní kí n wí fún ọ pé, ‘Ṣé o rí gbogbo àwọn ọmọ ogun yìí bí wọ́n ti pọ̀ tó? Wò ó! N óo fún ọ ní ìṣẹ́gun lórí wọn lónìí, o óo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA.’ ”

14 Ahabu bèèrè pé, “Ta ni yóo ṣáájú ogun?”

Wolii náà dáhùn pé, “OLUWA ní, àwọn iranṣẹ gomina ìpínlẹ̀ ni.”

Ahabu tún bèèrè pé, “Ta ni yóo bẹ̀rẹ̀ ogun náà?”

Wolii náà dáhùn pé, “Ìwọ gan-an ni.”

15 Ọba bá pe gbogbo àwọn iranṣẹ tí wọ́n wà lábẹ́ àwọn gomina ìpínlẹ̀ jọ, gbogbo wọn jẹ́ ojilerugba ó dín mẹjọ (232), ó sì pe gbogbo àwọn ọmọ ogun Israẹli jọ, gbogbo wọ́n jẹ́ ẹẹdẹgbaarin (7,000).

16 Nígbà tí ó di ọ̀sán, wọ́n kó ogun jáde, bí Benhadadi ọba ati àwọn ọba mejilelọgbọn tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ ti ń mu ọtí àmupara ninu àgọ́ wọn.

17 Àwọn ọ̀dọ́ ọmọ ogun ni wọ́n ṣáájú ogun Israẹli, wọ́n bá lọ ṣígun bá Benhadadi. Àwọn amí tí ọba Benhadadi rán jáde lọ ròyìn fún un pé, àwọn eniyan kan ń jáde bọ̀ láti ìlú Samaria.

18 Ó bá pàṣẹ pé kí wọ́n mú wọn láàyè, wọ́n ìbáà máa bọ̀ wá jagun, wọn ìbáà sì máa bọ̀ wá sọ̀rọ̀ alaafia.

19 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ ogun ṣe jáde ní ìlú: àwọn ọ̀dọ́ ọmọ ogun ni wọ́n ṣáájú ogun, lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ ogun Israẹli tẹ̀lé wọn.

20 Olukuluku wọn pa ẹni tí ó dojú ìjà kọ. Àwọn ọmọ ogun Siria bá sá. Àwọn ọmọ ogun Israẹli sì ń lé wọn lọ. Ṣugbọn Benhadadi, ọba Siria, ti gun ẹṣin sá lọ, pẹlu àwọn jagunjagun tí wọ́n gun ẹṣin.

21 Ahabu ọba bá lọ sójú ogun, ó kó ọpọlọpọ ẹṣin ati kẹ̀kẹ́ ogun; ó ṣẹgun àwọn ọmọ ogun Siria, ó sì pa ọpọlọpọ ninu wọn.

22 Wolii náà tún tọ Ahabu ọba lọ, ó wí fún un pé, “Pada lọ kó àwọn ọmọ ogun rẹ jọ, kí o sì ṣètò dáradára; nítorí pé, ọba Siria yóo tún bá ọ jagun ní ìbẹ̀rẹ̀ àkókò òjò.”

Siria Tún Gbógun ti Israẹli Nígbà Keji

23 Àwọn oníṣẹ́ Benhadadi ọba wí fún un pé, “Oriṣa orí òkè ni oriṣa àwọn ọmọ Israẹli. Ìdí nìyí tí wọ́n fi ṣẹgun wa. Ṣugbọn bí a bá gbógun tì wọ́n ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, a óo ṣẹgun wọn.

24 Nítorí náà, mú àwọn ọba mejeejilelọgbọn kúrò ní ààyè wọn gẹ́gẹ́ bí olórí ogun, kí o sì fi àwọn ọ̀gágun gidi dípò wọn.

25 Kí o wá kó àwọn ọmọ ogun mìíràn jọ, kí wọ́n pọ̀ bí i ti àkọ́kọ́, kí ẹṣin ati kẹ̀kẹ́ ogun pọ̀ bákan náà. A óo bá àwọn ọmọ Israẹli jagun ní pẹ̀tẹ́lẹ̀; láìsí àní àní, a óo sì ṣẹgun wọn.”

Ọba Benhadadi gba ìmọ̀ràn wọn, ó sì ṣe ohun tí wọ́n wí.

26 Ní ọdún tí ó tẹ̀lé e, ní ìbẹ̀rẹ̀ àkókò òjò, ó kó àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jọ, ó sì kó wọn lọ sí ìlú Afeki, láti gbógun ti àwọn ọmọ Israẹli.

27 Wọ́n kó àwọn ọmọ ogun Israẹli náà jọ, wọ́n sì wá àwọn ohun ìjà ogun fún wọn. Àwọn náà jáde sójú ogun, wọ́n pàgọ́ tiwọn siwaju àwọn ọmọ ogun Siria, wọ́n wá dàbí agbo ewúrẹ́ meji kéékèèké níwájú àwọn ọmọ ogun Siria tí wọ́n tò lọ rẹrẹẹrẹ ninu pápá.

28 Wolii kan tọ Ahabu lọ, ó sì wí fún un pé, “OLUWA ní kí n wí fún ọ pé, ‘Nítorí pé àwọn ará Siria sọ pé, “ọlọrun orí òkè ni OLUWA, kì í ṣe Ọlọrun àfonífojì,” nítorí náà ni n óo ṣe fún ọ ní ìṣẹ́gun lórí ọ̀pọ̀ eniyan wọnyi, o óo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA.’ ”

29 Àgọ́ àwọn ọmọ ogun Israẹli ati ti àwọn ọmọ ogun Siria kọjú sí ara wọn, wọn kò sì kúrò ní ààyè wọn fún ọjọ́ meje. Nígbà tí ó di ọjọ́ keje wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí jagun. Àwọn ọmọ ogun Israẹli pa ọ̀kẹ́ marun-un (100,000) ọmọ ogun tí wọn ń fi ẹsẹ̀ rìn lára àwọn ti Siria ní ọjọ́ kan.

30 Àwọn ọmọ ogun Siria yòókù sì sá lọ sí ìlú Afeki; odi ìlú náà sì wó pa ọ̀kẹ́ kan ati ẹẹdẹgbaarin (27,000) tí ó kù ninu wọn.

Benhadadi pàápàá sá wọ inú ìlú lọ, ó sì sá pamọ́ sinu yàrá ní ilé kan.

31 Àwọn oníṣẹ́ rẹ̀ wí fún un pé, “A gbọ́ pé àwọn ọba Israẹli a máa ní ojú àánú, jẹ́ kí á sán aṣọ ọ̀fọ̀ mọ́dìí, kí á wé okùn mọ́ ara wa lórí, kí á sì lọ sọ́dọ̀ ọba Israẹli, bóyá yóo dá ẹ̀mí rẹ sí.”

32 Nítorí náà, wọ́n sán aṣọ ọ̀fọ̀ mọ́dìí, wọ́n sì wé okùn mọ́ ara wọn lórí. Wọ́n bá tọ Ahabu ọba lọ, wọ́n ní, “Benhadadi, iranṣẹ rẹ, ní kí á jíṣẹ́ fún ọ pé kí o jọ̀wọ́ kí o dá ẹ̀mí òun sí.”

Ahabu bá dáhùn pé, “Ó ṣì wà láàyè? Arakunrin mi ni!”

33 Àwọn iranṣẹ Benhadadi ti ń ṣọ́ Ahabu fún àmì rere kan tẹ́lẹ̀. Nígbà tí Ahabu ti fẹnu kan “Arakunrin”, kíá ni wọ́n ti gba ọ̀rọ̀ yìí mọ́ ọn lẹ́nu, wọ́n ní, “Bẹ́ẹ̀ ni, arakunrin rẹ ni Benhadadi.”

Ahabu wí fún wọn pé, “Ẹ lọ mú un wá.” Nígbà tí Benhadadi dé, Ahabu ní kí ó wọ inú kẹ̀kẹ́ ogun pẹlu òun.

34 Benhadadi bá wí fún un pé, “N óo dá àwọn ìlú tí baba mi gbà lọ́wọ́ baba rẹ pada fún ọ, o óo sì lè kọ́ àwọn ilé ìtajà fún ara rẹ ní ìlú Damasku gẹ́gẹ́ bí baba mi ti ṣe ní ìlú Samaria.”

Ahabu dá a lóhùn pé, “Bí o bá ṣe ohun tí o wí yìí, n óo dá ọ sílẹ̀.” Ahabu bá bá a dá majẹmu, ó sì fi sílẹ̀ kí ó máa lọ.

Wolii kan Dá Ahabu lẹ́bi

35 OLUWA pàṣẹ fún ọ̀kan ninu àwọn ọmọ ẹgbẹ́ wolii kan, pé kí ó sọ fún wolii ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ kan pé kí ó jọ̀wọ́ kí ó lu òun, ṣugbọn wolii náà kọ̀, kò lù ú.

36 Ni ó bá wí fún un pé, “Nítorí pé o ṣàìgbọràn sí àṣẹ OLUWA, bí o bá ti ń kúrò lọ́dọ̀ mi gẹ́lẹ́ ni kinniun yóo pa ọ́.” Bí ó sì ti kúrò lóòótọ́, kinniun kan yọ sí i, ó sì pa á.

37 Wolii yìí rí ọkunrin mìíràn, o sì bẹ̀ ẹ́ pé, “Lù mí.” Ọkunrin yìí lù ú, lílù náà pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi pa á lára.

38 Wolii yìí bá mú aṣọ kan, ó fi wé ojú rẹ̀. Ó yíra pada, kí ẹnikẹ́ni má baà mọ̀ ọ́n, ó sì lọ dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà de ìgbà tí ọba Israẹli yóo kọjá.

39 Bí ọba ti ń kọjá lọ, wolii yìí kígbe pé, “Kabiyesi, nígbà tí mò ń jà lójú ogun, ọmọ ogun ẹlẹgbẹ́ mi kan mú ọ̀tá kan tí ó mú ní ìgbèkùn wá sọ́dọ̀ mi, ó ní kí n máa ṣọ́ ọkunrin yìí, ó ní bí ó bá sá lọ, èmi ni n óo kú dípò rẹ̀. Bí bẹ́ẹ̀ sì kọ́, mo níláti san ìwọ̀n talẹnti fadaka kan gẹ́gẹ́ bí owó ìtanràn.

40 Ṣugbọn níbi tí mo ti ń lọ sókè sódò, tí mò ń ṣe àwọn nǹkan mìíràn, ọkunrin yìí sá lọ.”

Ọba dá a lóhùn pé, “Ìwọ náà ti dá ara rẹ lẹ́jọ́, bẹ́ẹ̀ gan-an ni yóo sì rí.”

41 Wolii náà sáré tu aṣọ tí ó fi wé ojú, lẹsẹkẹsẹ ọba sì mọ̀ pé ọ̀kan ninu àwọn wolii ni.

42 Wolii náà bá wí fún ọba pé, “OLUWA ní, nítorí pé o jẹ́ kí ẹni tí mo ti pinnu láti pa sá lọ, ẹ̀mí rẹ ni n óo fi dípò ẹ̀mí rẹ̀, n óo sì pa àwọn eniyan rẹ dípò àwọn eniyan rẹ̀.”

43 Ọba bá pada lọ sí ààfin rẹ̀ ní Samaria, pẹlu ìpayà ati ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn.

Categories
ÀWỌN ỌBA KINNI

ÀWỌN ỌBA KINNI 21

Ọgbà Àjàrà Naboti

1 Ọkunrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Naboti, ará Jesireeli, ní ọgbà àjàrà kan. Ní Jesireeli ni ọgbà yìí wà, lẹ́bàá ààfin Ahabu, ọba Samaria.

2 Ní ọjọ́ kan, Ahabu pe Naboti ó ní, “Fún mi ni ọgbà àjàrà rẹ, mo fẹ́ lo ilẹ̀ náà fún ọgbà ewébẹ̀ nítorí ó súnmọ́ tòsí ààfin mi. N óo fún ọ ní ọgbà àjàrà tí ó dára ju èyí lọ dípò rẹ̀, tabi tí ó bá sì wù ọ́, n óo san owó rẹ̀ fún ọ.”

3 Naboti dáhùn pé, “Ọwọ́ àwọn baba ńlá mi ni mo ti jogún ọgbà àjàrà yìí; OLUWA má jẹ́ kí n rí ohun tí n óo fi gbé e fún ọ.”

4 Ahabu bá pada lọ sílé pẹlu ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn ati ibinu, nítorí ohun tí Naboti ará Jesireeli wí fún un. Ó dùbúlẹ̀ lórí ibùsùn rẹ̀, ó kọjú sí ògiri, kò sì jẹun.

5 Jesebẹli, aya rẹ̀, wọlé tọ̀ ọ́ lọ, ó sì bi í pé, “Kí ló dé tí ọkàn rẹ fi rẹ̀wẹ̀sì tóbẹ́ẹ̀ tí o kò fi jẹun?”

6 Ahabu dá a lóhùn pé, “Mo sọ fún Naboti pé mo fẹ́ ra ọgbà àjàrà rẹ̀, tabi bí ó bá fẹ́, kí ó jẹ́ kí n fún un ni òmíràn dípò rẹ̀; ṣugbọn ó ní òun kò lè fún mi ní ọgbà àjàrà òun.”

7 Jesebẹli, aya rẹ̀ dá a lóhùn pé, “Họ́wù! Ṣebí ìwọ ni ọba Israẹli, àbí ìwọ kọ́? Dìde nílẹ̀ kí o jẹun, kí o sì jẹ́ kí inú rẹ dùn, n óo gba ọgbà àjàrà Naboti fún ọ.”

8 Jesebẹli bá kọ ìwé ní orúkọ Ahabu, ó fi òǹtẹ̀ Ahabu tẹ̀ ẹ́, ó fi ranṣẹ sí àwọn àgbààgbà ati àwọn eniyan ńláńlá ní ìlú tí Naboti ń gbé.

9 Ohun tí ó kọ sinu ìwé náà ni pé, “Ẹ kéde ọjọ́ ààwẹ̀ kan, ẹ pe àwọn eniyan jọ, ẹ sì fi Naboti jókòó ní ipò ọlá.

10 Kí ẹ wá àwọn eniyankeniyan meji kan tí wọ́n ya aṣa, kí wọ́n jókòó níwájú rẹ̀, kí wọ́n sì fi ẹ̀sùn kàn án pé, ó bú Ọlọrun ati ọba. Lẹ́yìn náà, ẹ mú un jáde sẹ́yìn odi ìlú, kí ẹ sì sọ ọ́ lókùúta pa.”

11 Àwọn àgbààgbà ati àwọn eniyan ńláńlá tí wọn ń gbé ìlú náà ṣe bí Jesebẹli ti ní kí wọ́n ṣe ninu ìwé tí ó kọ ranṣẹ sí wọn.

12 Wọ́n kéde ọjọ́ ààwẹ̀ kan, wọ́n pe àwọn eniyan jọ, wọ́n sì fún Naboti ní ipò ọlá láàrin wọn.

13 Àwọn eniyankeniyan meji tí wọ́n ya aṣa yìí jókòó níwájú rẹ̀, wọ́n sì purọ́ mọ́ ọn lójú gbogbo eniyan pé ó bú Ọlọrun ati ọba. Wọ́n bá fà á jáde sẹ́yìn odi ìlú, wọ́n sì sọ ọ́ lókùúta pa.

14 Lẹ́yìn náà wọ́n ranṣẹ sí Jesebẹli pé àwọn ti sọ Naboti lókùúta pa.

15 Bí Jesebẹli ti gbọ́ pé wọ́n ti sọ Naboti lókùúta pa, ó sọ fún Ahabu pé, “Gbéra nisinsinyii, kí o sì lọ gba ọgbà àjàrà tí Naboti kọ̀ láti tà fún ọ, nítorí pé ó ti kú.”

16 Lẹsẹkẹsẹ bí Ahabu ti gbọ́ pé Naboti ti kú, ó lọ sí ibi ọgbà àjàrà náà, ó sì gbà á.

17 OLUWA bá sọ fún Elija wolii ará Tiṣibe pé,

18 “Lọ bá Ahabu, ọba Israẹli, tí ń gbé Samaria; o óo bá a ninu ọgbà àjàrà Naboti, tí ó lọ gbà.

19 Sọ pé, OLUWA ní kí o sọ fún un pé ṣé o ti pa ọkunrin yìí, o sì ti gba ọgbà àjàrà rẹ̀? Wí fún un pé, mo ní, ibi tí ajá ti lá ẹ̀jẹ̀ Naboti gan-an ni ajá yóo ti lá ẹ̀jẹ̀ tirẹ̀ náà.”

20 Nígbà tí Ahabu rí Elija, ó bi í pé, “O tún ti rí mi kọ́, ìwọ ọ̀tá mi?”

Elija bá dá a lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, mo tún ti rí ọ; nítorí pé o ti fa ara rẹ kalẹ̀ láti ṣe iṣẹ́ burúkú níwájú OLUWA.

21 OLUWA ní òun óo jẹ́ kí ibi bá ọ, òun óo pa ọ́ rẹ́, òun ó sì run gbogbo ọkunrin tí ń bẹ ninu ìdílé rẹ, ati ẹrú ati ọmọ.

22 Ó ní bí òun ti ṣe ìdílé Jeroboamu, ọmọ Nebati, ati ti Baaṣa, ọmọ Ahija, bẹ́ẹ̀ ni òun óo ṣe ìdílé rẹ; nítorí o ti jẹ́ kí àwọn ọmọ Israẹli dẹ́ṣẹ̀, o sì ti mú òun OLUWA bínú.

23 Ní ti Jesebẹli, OLUWA ní, ajá ni yóo jẹ òkú rẹ̀ láàrin ìlú Jesireeli.

24 Ẹni tí ó bá kú sí ààrin ìlú ninu ìdílé ìwọ Ahabu, ajá ni yóo jẹ òkú rẹ̀, ẹni tí ó bá sì kú sinu pápá, àwọn ẹyẹ ni yóo jẹ òkú rẹ̀.”

25 (Kò sí ẹni tí ó fi ara rẹ̀ fún iṣẹ́ burúkú lójú OLUWA gẹ́gẹ́ bíi Ahabu, tí Jesebẹli aya rẹ̀, ń tì gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n láti ṣe iṣẹ́ burúkú.

26 Gbogbo ọ̀nà ìríra tí àwọn ará Amori ń gbà bọ oriṣa ni Ahabu pàápàá ń gbà bọ oriṣa rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni lílé sì ni OLUWA lé àwọn ará Amori jáde kúrò ní ilẹ̀ Kenaani fún àwọn ọmọ Israẹli nígbà tí wọn ń bọ̀.)

27 Nígbà tí Elija parí ọ̀rọ̀ rẹ̀, Ahabu fa aṣọ rẹ̀ ya láti fi ìbànújẹ́ rẹ̀ hàn, ó bọ́ wọn kúrò, ó sì wọ aṣọ ọ̀fọ̀. Ó gbààwẹ̀, orí aṣọ ọ̀fọ̀ ni ó sì ń sùn; ó sì ń káàkiri pẹlu ìdoríkodò ati ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn.

28 OLUWA tún sọ fún Elija pé,

29 “Ǹjẹ́ o ṣe akiyesi bí Ahabu ti rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ níwájú mi? Nítorí pé ó ti rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ báyìí, n kò ní jẹ́ kí ibi tí mo wí ṣẹlẹ̀ nígbà ayé rẹ̀. Ó di ìgbà ayé ọmọ rẹ̀ kí n tó jẹ́ kí ibi ṣẹlẹ̀ sí ìdílé rẹ̀.”

Categories
ÀWỌN ỌBA KINNI

ÀWỌN ỌBA KINNI 22

Wolii Mikaaya Kìlọ̀ fún Ahabu

1 Fún ọdún mẹta lẹ́yìn èyí, kò sí ogun rárá láàrin ilẹ̀ Israẹli ati ilẹ̀ Siria.

2 Nígbà tí ó di ọdún kẹta, Jehoṣafati, ọba Juda, lọ bẹ Ahabu, ọba Israẹli wò.

3 Ahabu bi àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ pé, “Ǹjẹ́ ẹ mọ̀ pé àwa ni a ni ìlú Ramoti Gileadi? A kò sì ṣe ohunkohun láti gbà á pada lọ́wọ́ ọba Siria.”

4 Ó bi Jehoṣafati pé, “Ṣé o óo bá mi lọ, kí á jọ lọ gbógun ti ìlú Ramoti Gileadi?”

Jehoṣafati bá dá a lóhùn pé, “Bí ó bá ti yá ọ, ó yá mi. Tìrẹ ni àwọn eniyan mi, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ẹṣin mi pẹlu.”

5 Jehoṣafati fi ṣugbọn kan kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé, “Jẹ́ kí a kọ́kọ́ wádìí lọ́wọ́ OLUWA ná.”

6 Ahabu ọba Israẹli bá pe àwọn wolii bí irinwo (400) jọ, ó bi wọ́n pé ṣé kí òun lọ gbógun ti ìlú Ramoti Gileadi àbí kí òun má lọ?

Wọ́n dá a lóhùn pé, “Máa lọ, nítorí OLUWA yóo jẹ́ kí ọwọ́ rẹ tẹ̀ ẹ́, yóo fún ọ ní ìṣẹ́gun lórí rẹ̀.”

7 Ṣugbọn Jehoṣafati bèèrè pé, “Ṣé kò tún sí wolii OLUWA mìíràn mọ́, tí a lè wádìí lọ́dọ̀ rẹ̀?”

8 Ahabu dá a lóhùn pé, “Ẹnìkan tí ó kù, tí ó tún lè bá wa wádìí lọ́dọ̀ OLUWA ni Mikaaya ọmọ Imila, ṣugbọn mo kórìíra rẹ̀; nítorí pé kò sọ àsọtẹ́lẹ̀ rere nípa mi rí, àfi burúkú.”

Jehoṣafati dá a lóhùn pé, “Kabiyesi, má wí bẹ́ẹ̀.”

9 Ahabu bá pàṣẹ fún ọ̀kan ninu àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ ní ààfin pé kí ó lọ pe Mikaaya, ọmọ Imila, wá kíákíá.

10 Ọba Israẹli ati Jehoṣafati ọba Juda wọ aṣọ ìgúnwà wọn, wọ́n sì jókòó lórí ìtẹ́ wọn, ní ibi ìpakà tí ó wà lẹ́nu bodè Samaria; gbogbo àwọn wolii sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ àsọtẹ́lẹ̀ níwájú wọn.

11 Ọ̀kan ninu wọn tí ń jẹ́ Sedekaya, ọmọ Kenaana fi irin ṣe ìwo, ó sì wí fún Ahabu pé, “OLUWA ní kí n wí fún ọ pé, ohun tí ìwọ óo fi bá àwọn ará Siria jà nìyí títí tí o óo fi ṣẹgun wọn patapata.”

12 Nǹkan kan náà ni gbogbo àwọn wolii yòókù ń wí, gbogbo wọn ní kí Ahabu lọ gbógun ti Ramoti Gileadi, wọ́n ní OLUWA yóo fún un ní ìṣẹ́gun.

13 Iranṣẹ tí ọba rán lọ pe Mikaaya wí fún un pé, “Gbogbo àwọn wolii yòókù ni wọ́n ti fi ohùn ṣọ̀kan tí wọ́n sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ rere fún ọba, ìwọ náà jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ ó bá tiwọn mu, kí o sọ àsọtẹ́lẹ̀ rere.”

14 Ṣugbọn Mikaaya dáhùn pé, “OLUWA alààyè, ń gbọ́! Ohun tí OLUWA bá wí fún mi ni n óo sọ.”

15 Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ ọba, ọba bi í pé, “Mikaaya, ṣé kí á lọ gbógun ti Ramoti Gileadi ni, àbí kí á má lọ?”

Mikaaya dáhùn pé, “Lọ gbógun tì í, OLUWA yóo fún ọ ní ìṣẹ́gun.”

16 Ṣugbọn Ahabu tún bi í pé, “Ìgbà mélòó ni n óo sọ fún ọ pé, nígbà tí o bá sọ̀rọ̀ fún mi ní orúkọ OLUWA, kí o máa sọ òtítọ́ fún mi?”

17 Mikaaya bá dáhùn pé, “Mo rí àwọn ọmọ ogun Israẹli tí wọ́n fọ́n káàkiri gbogbo orí òkè, bí aguntan tí kò ní olùṣọ́. OLUWA sì wí pé, ‘Àwọn eniyan wọnyi kò ní olórí, kí olukuluku wọn pada lọ sí ilé ní alaafia.’ ”

18 Ahabu bá wí fún Jehoṣafati pé, “Ṣebí mo ti sọ fún ọ pé kì í sọ àsọtẹ́lẹ̀ rere nípa mi, àfi burúkú?”

19 Mikaaya dáhùn pé, “Ó dára, fetí sílẹ̀, kí o gbọ́ ohun tí OLUWA wí, mo rí i tí OLUWA jókòó lórí ìtẹ́ rẹ̀ ní ọ̀run, gbogbo ogun ọ̀run sì dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ ọ̀tún ati tòsì,

20 OLUWA bèèrè pé, ‘Ta ni yóo lọ tan Ahabu jẹ, kí ó lè lọ sí Ramoti Gileadi kí wọ́n sì pa á níbẹ̀?’ Bí angẹli kan ti ń sọ ọ̀kan bẹ́ẹ̀ ni òmíràn sì ń sọ nǹkan mìíràn.

21 Ẹ̀mí kan bá jáde siwaju OLUWA, ó ní, ‘N óo lọ tàn án jẹ.’

22 OLUWA bá bi í pé, ‘Ọgbọ́n wo ni o óo dá?’ Ẹ̀mí náà dáhùn pé, ‘N óo mú kí gbogbo àwọn wolii Ahabu purọ́ fún un.’ OLUWA bá dáhùn pé, ‘Lọ tàn án jẹ, o óo ṣe àṣeyọrí.’

23 “Nítorí náà, gbọ́ nisinsinyii, OLUWA ni ó jẹ́ kí àwọn wolii wọnyi máa purọ́ fún ọ, nítorí pé ó ti pinnu láti jẹ́ kí ibi bá ọ.”

24 Sedekaya wolii, ọmọ Kenaana bá súnmọ́ Mikaaya, ó gbá a létí, ó ní, “Ọ̀nà wo ni Ẹ̀mí OLUWA gbà fi mí sílẹ̀, tí ó sì ń bá ìwọ sọ̀rọ̀.”

25 Mikaaya bá dá a lóhùn pé, “O óo rí i nígbà tí ó bá di ọjọ́ náà, tí o bá sá wọ yàrá inú patapata lọ, láti fi ara pamọ́.”

26 Ọba Israẹli bá dáhùn pé, “Ẹ mú Mikaaya pada lọ fún Amoni, gomina ìlú yìí, ati Joaṣi ọmọ ọba.

27 Ẹ ní, èmi ọba ni mo ní kí ẹ sọ fún wọn pé, kí wọ́n jù ú sinu ẹ̀wọ̀n, kí wọn sì máa fún un ní àkàrà lásán ati omi, títí tí n óo fi pada dé ní alaafia.”

28 Mikaaya bá dáhùn pé, “Bí o bá pada dé ní alaafia, a jẹ́ pé kì í ṣe OLUWA ló gba ẹnu mi sọ̀rọ̀.” Ó ní, “Gbogbo eniyan, ṣé ẹ gbọ́ ohun tí mo wí?”

Ikú Ahabu

29 Ahabu, ọba Israẹli, ati Jehoṣafati, ọba Juda, bá lọ gbógun ti ìlú Ramoti Gileadi.

30 Ahabu wí fún Jehoṣafati pé, “Bí a ti ń lọ sí ojú ogun yìí, n óo paradà, kí ẹnikẹ́ni má baà dá mi mọ̀. Ṣugbọn ìwọ, wọ aṣọ oyè rẹ.” Ahabu, ọba Israẹli, bá paradà, ó sì lọ sójú ogun.

31 Ọba Siria ti pàṣẹ fún àwọn olórí kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ mejeejilelọgbọn, pé kí wọ́n má lépa ẹnikẹ́ni lójú ogun, àfi ọba Israẹli nìkan.

32 Nítorí náà, nígbà tí wọ́n rí Jehoṣafati ọba, wọ́n ní, “Dájúdájú ọba Israẹli nìyí.” Wọ́n bá yipada láti bá a jà; ṣugbọn Jehoṣafati kígbe.

33 Nígbà tí wọ́n mọ̀ pé kì í ṣe òun ni ọba Israẹli, wọ́n bá pada lẹ́yìn rẹ̀.

34 Ṣugbọn ọ̀kan ninu àwọn ọmọ ogun Siria déédé ta ọfà rẹ̀, ọfà náà sì bá Ahabu ọba níbi tí àwọn irin ìgbàyà rẹ̀ ti fi ẹnu ko ara wọn. Ó bá wí fún ẹni tí ń wa kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ pé kí ó gbé òun kúrò lójú ogun, nítorí pé òun ti fara gbọgbẹ́.

35 Ogun gbóná gidigidi ní ọjọ́ náà. Ọwọ́ ni wọ́n fi ti ọba Ahabu ninu kẹ̀kẹ́ ogun tí ó wà, tí ó sì kọjú sí àwọn ará Siria. Nígbà tí yóo sì fi di ìrọ̀lẹ́, ó ti kú. Ẹ̀jẹ̀ tí ń ṣàn láti ojú ọgbẹ́ rẹ̀ sì ti dà sí ìsàlẹ̀ kẹ̀kẹ́ ogun náà.

36 Nígbà tí oòrùn ń lọ wọ̀, wọ́n kéde fún gbogbo àwọn ọmọ ogun pé, “Kí olukuluku pada sí agbègbè rẹ̀! Kí kaluku kọrí sí ìlú rẹ̀!”

37 Bẹ́ẹ̀ ni Ahabu ọba ṣe kú; wọ́n gbé òkú rẹ̀ lọ sí Samaria, wọ́n sì sin ín sibẹ.

38 Wọ́n lọ fọ kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ ní adágún Samaria, àwọn ajá lá ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, àwọn aṣẹ́wó sì lọ wẹ̀ ninu adágún náà gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti sọ tẹ́lẹ̀ pé yóo rí.

39 Gbogbo àwọn nǹkan yòókù tí Ahabu ọba ṣe, ati àkọsílẹ̀ bí ó ṣe fi eyín erin ṣe iṣẹ́ ọnà sí ààfin rẹ̀, ati ti gbogbo ìlú tí ó tẹ̀dó, wà ninu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli.

40 Lẹ́yìn tí òun kú ni Ahasaya ọmọ rẹ̀ gun orí oyè.

Jehoṣafati, Ọba Juda

41 Ní ọdún kẹrin tí Ahabu, ọba Israẹli, gun orí oyè, ni Jehoṣafati, ọmọ Asa, gun orí oyè ní ilẹ̀ Juda.

42 Ọmọ ọdún marundinlogoji ni Jehoṣafati nígbà tí ó jọba, ó sì wà lórí oyè ní Jerusalẹmu fún ọdún mẹẹdọgbọn. Asuba ọmọ Ṣilihi ni ìyá rẹ̀.

43 Ohun tí ó dára lójú OLUWA, tí Asa baba rẹ̀ ṣe ni òun náà ṣe; ṣugbọn kò wó àwọn pẹpẹ ìrúbọ tí wọ́n wà káàkiri. Àwọn eniyan tún ń rúbọ, wọ́n sì tún ń sun turari níbẹ̀.

44 Jehoṣafati bá ọba Israẹli ṣọ̀rẹ́, alaafia sì wà láàrin wọn.

45 Gbogbo nǹkan yòókù tí Jehoṣafati ṣe, gbogbo iṣẹ́ akikanju rẹ̀, ati gbogbo ogun tí ó jà, wà ninu àkọsílẹ̀ Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Juda.

46 Gbogbo àwọn aṣẹ́wó ọkunrin tí ó kù ní ilé àwọn oriṣa láti àkókò Asa, baba rẹ̀, ni ó parun ní ilẹ̀ náà.

47 Kò sí ọba ní ilẹ̀ Edomu. Adelé ọba kan ní ń ṣàkóso ilẹ̀ náà.

48 Jehoṣafati ọba kan àwọn ọkọ̀ ojú omi bíi ti ìlú Taṣiṣi, láti kó wọn lọ sí ilẹ̀ Ofiri láti lọ wá wúrà. Ṣugbọn wọn kò lè lọ nítorí pé àwọn ọkọ̀ náà bàjẹ́ ní Esiongeberi.

49 Ahasaya ọba Israẹli, ọmọ Ahabu, ọba Israẹli sọ fún Jehoṣafati pé kí àwọn eniyan òun bá àwọn eniyan rẹ̀ tu ọkọ̀ lọ, ṣugbọn Jehoṣafati kò gbà.

50 Nígbà tí ó yá, Jehoṣafati kú, wọ́n sì sin ín sí ibojì àwọn ọba, ní ìlú Dafidi, baba ńlá rẹ̀. Jehoramu ọmọ rẹ̀ sì gorí oyè dípò rẹ̀.

Ahasaya, Ọba Israẹli

51 Ní ọdún kẹtadinlogun tí Jehoṣafati, ọba Juda, gun orí oyè ni Ahasaya, ọmọ Ahabu, gun orí oyè ní ilẹ̀ Israẹli, ó sì jọba ní Samaria fún ọdún meji.

52 Ó ṣe nǹkan burúkú lójú OLUWA, ó tẹ̀lé àpẹẹrẹ burúkú Ahabu, baba rẹ̀, ati ti Jesebẹli, ìyá rẹ̀, ati ti Jeroboamu, ọmọ Nebati, àwọn tí wọ́n jẹ́ kí Israẹli dẹ́ṣẹ̀.

53 Ó bọ oriṣa Baali, ó sì mú OLUWA Ọlọrun Israẹli bínú ní gbogbo ọ̀nà bí baba rẹ̀ ti ṣe.