Categories
ÀWỌN ỌBA KINNI

ÀWỌN ỌBA KINNI Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ìwé Àwọn Ọba Kinni

jẹ́ ìtẹ̀síwájú ìtàn àwọn ọba Israẹli, tí ìtàn wọn bẹ̀rẹ̀ ninu àwọn Ìwé Samuẹli. Ọ̀nà mẹta pataki ni a lè pín ìtàn inú ìwé yìí sí: (1) Bí Solomoni ṣe jọba Israẹli ati ti Juda; ati ikú Dafidi, baba rẹ̀. (2) Àkókò ìjọba ati àṣeyọrí Solomoni–ní pataki àṣeyọrí kíkọ́ Tẹmpili ní Jerusalẹmu. (3) Pípín orílẹ̀-èdè náà sí meji, àwọn orílẹ̀-èdè ìhà àríwá ati ti ìhà gúsù; ati ìtàn àwọn ọba tí wọ́n jẹ lórí ìpín mejeeji láti ìgbà náà títí di ààrin sẹntiuri kẹsan-an, ká tó bí OLUWA wa (mid 9th Century B.C.)

Ninu ìwé Àwọn Ọba mejeeji ìhà tí ọba kọ̀ọ̀kan bá kọ sí Ọlọrun ni wọ́n fi ń ṣe ìdájọ́ rẹ̀. Bákan náà, àṣeyọrí orílẹ̀-èdè wọn wà lọ́wọ́ irú ìhà tí wọ́n bá kọ sí Ọlọrun. Ní ìdà keji ẹ̀wẹ̀, ìjìyà ni ìwà àgbèrè ati àìgbọràn máa ń kó bá wọn. Gbogbo ọba tí ó jẹ ní ìhà àríwá ni wọn kò ṣe dáradára, ṣugbọn ní ti àwọn ọba Juda, àwọn mìíràn ninu wọn kò ṣe dáradára, àwọn mìíràn sì ṣe àṣeyọrí.

Ninu ìwé yìí àwọn wolii OLUWA ni wọ́n kó ipa pataki jùlọ, àwọn ni akikanju agbẹnusọ fún Ọlọrun, tí máa ń kìlọ̀ fún àwọn eniyan pé kí wọn má bọ̀rìṣà, kí wọ́n sì máa pa òfin Ọlọrun mọ. Wolii Elija jẹ́ akọni láàrin wọn; pàápàá nítorí ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ṣẹ̀ láàrin òun ati àwọn alufaa Baali (orí 18).

Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí

Òpin ìjọba Dafidi 1:1–2:12

Solomoni jọba 2:13-46

Àkókò ìjọba Solomoni 3:1–11:43

a. Àwọn ọdún tí Solomoni kọ́kọ́ lò lórí oyè 3:1–4:34

b. Kíkọ́ Tẹmpili 5:1–8:66

d. Àwọn ọdún tí Solomoni lò kẹ́yìn lórí oyè 9:1–11:43

Pípín ìjọba orílẹ̀-èdè Israẹli sí meji 12:1–22:53

a. Àwọn ẹ̀yà àríwá yapa 12:1–14:20

b. Àwọn ọba Juda ati àwọn ti Israẹli 14:21–16:34

d. Wolii Elija 17:1–19:21

e. Ahabu Ọba Israẹli 20:1–22:40

ẹ. Jehoṣafati ọba Juda ati Ahasaya ọba Israẹli 22:41-53

Categories
ÀWỌN ỌBA KINNI

ÀWỌN ỌBA KINNI 1

Ìgbà Ogbó Dafidi

1 Ní àkókò yìí, Dafidi ọba ti di arúgbó. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé aṣọ tí ó nípọn ni wọ́n fi ń bò ó, òtútù a tún máa mú un.

2 Nítorí náà, àwọn iranṣẹ rẹ̀ wí fún un pé, “Kabiyesi, jẹ́ kí á wá ọdọmọbinrin kan fún ọ, tí yóo máa wà pẹlu rẹ, tí yóo sì máa tọ́jú rẹ. Yóo máa sùn tì ọ́ kí ara rẹ lè máa móoru.”

3 Nítorí náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí wá ọdọmọbinrin tí ó lẹ́wà gidigidi ní gbogbo ilẹ̀ Israẹli. Wọ́n rí ọdọmọbinrin arẹwà kan ní ìlú Ṣunemu, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Abiṣagi, wọ́n sì mú un tọ Dafidi wá.

4 Ọdọmọbinrin náà dára gan-an; ó wà lọ́dọ̀ ọba, ó ń tọ́jú rẹ̀, ṣugbọn ọba kò bá a lòpọ̀ rárá.

Adonija Fẹ́ Fi Ara Rẹ̀ Jọba

5 Adonija, ọmọ tí Hagiti bí fún Dafidi, bẹ̀rẹ̀ sí gbéraga, ó ń wí pé, “Èmi ni n óo jọba.” Ó bá lọ tọ́jú kẹ̀kẹ́ ogun, ati àwọn ẹlẹ́ṣin ati aadọta ọkunrin tí yóo máa sáré níwájú rẹ̀.

6 Adonija yìí ni wọ́n bí tẹ̀lé Absalomu, ó jẹ́ arẹwà ọkunrin; baba rẹ̀ kò sì fi ìgbà kan dojú kọ ọ́ kí ó bá a wí nítorí ohunkohun rí.

7 Adonija lọ jíròrò pẹlu Joabu, ọmọ Seruaya, ati Abiatari alufaa, àwọn mejeeji tẹ̀lé ọ̀rọ̀ rẹ̀, wọ́n sì ràn án lọ́wọ́.

8 Ṣugbọn Sadoku alufaa, ati Bẹnaya ọmọ Jehoiada, ati Natani wolii, ati Ṣimei, Rei, ati àwọn akọni Dafidi kò faramọ́ ohun tí Adonija ṣe, wọn kò sì sí lẹ́yìn rẹ̀.

9 Ní ọjọ́ kan, Adonija fi ọpọlọpọ aguntan, pẹlu akọ mààlúù, ati àbọ́pa mààlúù rúbọ níbi Àpáta Ejò, lẹ́bàá orísun Enrogeli, ó sì pe àwọn ọmọ ọba yòókù, àwọn arakunrin rẹ̀, ati gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ ọba ní ilẹ̀ Juda.

10 Ṣugbọn kò pe Natani wolii, tabi Bẹnaya, tabi àwọn akọni ninu àwọn jagunjagun ọba, tabi Solomoni, arakunrin rẹ̀.

Solomoni Jọba

11 Natani bá tọ Batiṣeba ìyá Solomoni lọ, ó bi í pé, “Ṣé o ti gbọ́ pé Adonija ọmọ Hagiti ti fi ara rẹ̀ jọba, Dafidi ọba kò sì mọ nǹkankan nípa rẹ̀.

12 Wá, jẹ́ kí n gbà ọ́ nímọ̀ràn kan, bí o bá fẹ́ràn ẹ̀mí rẹ, ati ẹ̀mí Solomoni, ọmọ rẹ.

13 Tọ Dafidi ọba lọ lẹsẹkẹsẹ, kí o sì bi í pé, ṣebí òun ni ó fi ìbúra ṣe ìlérí fún ọ pé Solomoni ọmọ rẹ ni yóo jọba lẹ́yìn rẹ̀? Kí ló dé tí Adonija fi di ọba?

14 Bí o bá ti ń bá ọba sọ̀rọ̀ ni n óo wọlé, n óo sì sọ pé òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ.”

15 Batiṣeba bá wọlé tọ ọba lọ ninu yàrá rẹ̀. (Ọba ti di arúgbó ní àkókò yìí, Abiṣagi ará Ṣunemu ni ó ń tọ́jú rẹ̀.)

16 Batiṣeba wólẹ̀ níwájú ọba, ó sì kí i tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀. Ọba bá bi í pé, “Kí ni o fẹ́ gbà?”

17 Ó dá ọba lóhùn, ó ní, “Kabiyesi, ìwọ ni o ṣe ìlérí fún èmi iranṣẹbinrin rẹ, tí o sì fi orúkọ OLUWA Ọlọrun rẹ búra pé, Solomoni ọmọ mi ni yóo jọba lẹ́yìn rẹ.

18 Ṣugbọn Adonija ti fi ara rẹ̀ jọba, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kabiyesi kò mọ nǹkankan nípa rẹ̀.

19 Ó ti fi ọpọlọpọ akọ mààlúù, ati aguntan, ati àbọ́pa mààlúù rúbọ. Ó pe gbogbo àwọn ọmọ ọba lọkunrin, ati Abiatari alufaa, ati Joabu balogun rẹ síbi àsè rẹ̀, ṣugbọn kò pe Solomoni, iranṣẹ rẹ.

20 Ojú rẹ ni gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ń wò báyìí, pé kí o fa ẹni tí o bá fẹ́ kí ó jọba lẹ́yìn rẹ kalẹ̀ fún wọn.

21 Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, gbàrà tí kabiyesi bá ti kú tán, bí wọ́n ti ń ṣe àwọn arúfin ni wọn yóo ṣe èmi ati Solomoni ọmọ rẹ.”

22 Bí ó ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́ ni Natani wolii wọlé.

23 Wọ́n bá sọ fún ọba pé Natani wolii ti dé. Nígbà tí Natani wọlé, ó wólẹ̀ níwájú ọba, ó sì dojúbolẹ̀.

24 Ó wí pé, “Kabiyesi, ṣé o ti kéde pé Adonija ni yóo jọba lẹ́yìn rẹ ni?

25 Ní òní olónìí yìí, ó ti fi ọpọlọpọ akọ mààlúù, ati aguntan, ati àbọ́pa mààlúù rúbọ. Ó pe gbogbo àwọn ọmọ ọba lọkunrin, ati Joabu balogun, ati Abiatari, alufaa. Bí mo ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́ yìí, gbogbo wọn wà níbi tí wọ́n ti ń jẹ, tí wọn ń mu, tí wọn ń pariwo pé, ‘Kí Adonija ọba kí ó pẹ́.’

26 Ṣugbọn kò pe èmi iranṣẹ rẹ sí ibi àsè náà, kò sì pe Sadoku alufaa, tabi Bẹnaya, ọmọ Jehoiada, tabi Solomoni iranṣẹ rẹ.

27 Ǹjẹ́ kabiyesi ha lè lọ́wọ́ sí irú nǹkan báyìí; kí ó má tilẹ̀ sọ ẹni tí yóo gun orí oyè lẹ́yìn rẹ̀ fún àwọn iranṣẹ rẹ̀?”

28 Dafidi ọba bá ní kí wọ́n pe Batiṣeba pada wọlé. Ó bá pada wá siwaju ọba.

29 Ọba bá búra fún un pé, “Mo ṣe ìlérí fún ọ ní orúkọ OLUWA Alààyè, tí ó gbà mí ninu gbogbo ìyọnu mi,

30 pé lónìí ni n óo mú ìbúra tí mo búra fún ọ ní orúkọ OLUWA Ọlọrun Israẹli ṣẹ, pé, Solomoni, ọmọ rẹ ni yóo jọba lẹ́yìn mi.”

31 Batiṣeba wólẹ̀ níwájú ọba, ó dojúbolẹ̀, ó ní, “Kabiyesi, oluwa mi, kí ẹ̀mí ọba ó gùn.”

32 Ọba bá ranṣẹ pe Sadoku, alufaa, ati Natani wolii, ati Bẹnaya ọmọ Jehoiada, gbogbo wọ́n sì pésẹ̀ sọ́dọ̀ ọba.

33 Ọba bá pàṣẹ fún wọn pé, “Ẹ kó gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ mi lẹ́yìn, kí ẹ sì gbé Solomoni gun ìbaaka mi, kí ẹ mú un lọ sí odò Gihoni,

34 kí Sadoku, alufaa ati Natani wolii, fi àmì òróró yàn án ní ọba níbẹ̀, lórí gbogbo Israẹli. Lẹ́yìn náà, kí ẹ fọn fèrè, kí ẹ sì hó pé, ‘Kí ẹ̀mí Solomoni, ọba, kí ó gùn!’

35 Lẹ́yìn náà, ẹ óo tẹ̀lé e pada wá síhìn-ín kí ó wá jókòó lórí ìtẹ́ mi; nítorí pé òun ni yóo jọba lẹ́yìn mi. Òun ni mo yàn láti jọba Israẹli ati Juda.”

36 Bẹnaya bá dáhùn pé, “Àṣẹ! Kí OLUWA Ọlọrun rẹ bá wa lọ́wọ́ sí i.

37 Bí OLUWA ti wà pẹlu kabiyesi, bẹ́ẹ̀ náà ni kí ó wà pẹlu Solomoni, kí ó sì mú kí ìgbà tirẹ̀ tún dára ju ìgbà ti kabiyesi, oluwa mi, Dafidi ọba lọ.”

38 Sadoku alufaa, ati Natani wolii, ati Bẹnaya, pẹlu àwọn ará Kereti ati àwọn ará Peleti tí wọn ń ṣọ́ ọba, bá gbé Solomoni gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ Dafidi ọba, wọ́n sì mú un lọ sí odò Gihoni.

39 Sadoku alufaa, bá mú ìwo tí wọ́n rọ òróró olifi sí, tí ó ti mú láti inú àgọ́ OLUWA jáde, ó sì ta òróró náà sí Solomoni lórí. Wọ́n fọn fèrè, gbogbo wọn sì hó pé, “Kí Solomoni, ọba, kí ó pẹ́.”

40 Gbogbo eniyan bá tẹ̀lé e pada, wọ́n ń fọn fèrè, wọ́n ń hó fún ayọ̀. Ariwo tí wọn ń pa pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí ilẹ̀ fi mì tìtì.

41 Bí Adonija ati gbogbo àwọn tí ó pè sí ibi àsè rẹ̀ ti ń parí àsè, wọ́n gbọ́ ariwo náà. Nígbà tí Joabu gbọ́ fèrè, ó bèèrè pé, “Kí ni ìtumọ̀ gbogbo ariwo tí wọn ń pa ninu ìlú yìí?”

42 Kí ó tó dákẹ́ ọ̀rọ̀ sísọ, Jonatani, ọmọ Abiatari, alufaa, dé. Adonija sọ fún un pé, “Máa wọlé bọ̀; eniyan rere ni ìwọ, ó sì níláti jẹ́ pé ìròyìn rere ni ò ń mú bọ̀.”

43 Jonatani bá dáhùn pé, “Rárá o, kabiyesi ti fi Solomoni jọba!

44 Ó sì ti rán Sadoku alufaa, ati Natani wolii, ati Bẹnaya ati àwọn tí wọn ń ṣọ́ ọba pé kí wọ́n tẹ̀lé Solomoni, wọ́n sì ti gbé e gun orí ìbaaka ọba.

45 Sadoku alufaa ati Natani wolii sì ti fi àmì òróró yàn án ní ọba ní odò Gihoni. Lẹ́yìn náà, wọ́n ti pada lọ sí ààrin ìlú, wọ́n sì ń hó fún ayọ̀. Ariwo sì ti gba gbogbo ìlú. Ìdí rẹ̀ ni ẹ fi ń gbọ́ ariwo.

46 Solomoni ti gúnwà lórí ìtẹ́ ọba.

47 Kí ló tún kù! Gbogbo àwọn iranṣẹ ọba ni wọ́n ti lọ kí Dafidi ọba, pé, ‘Kí Ọlọrun rẹ mú kí Solomoni lókìkí jù ọ́ lọ, kí ìjọba rẹ̀ sì ju tìrẹ lọ.’ Ọba bá tẹríba, ó sì sin Ọlọrun lórí ibùsùn rẹ̀,

48 ó ní ‘Ìyìn ni fún OLUWA Ọlọrun Israẹli, tí ó jẹ́ kí ọ̀kan ninu àwọn ọmọ mi jọba lónìí, tí ó sì jẹ́ kí n fi ojú mi rí i.’ ”

49 Ẹ̀rù ba gbogbo àwọn tí wọ́n lọ bá Adonija jẹ àsè, gbogbo wọ́n bá dìde, olukuluku bá tirẹ̀ lọ.

50 Ẹ̀rù Solomoni ba Adonija tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi sá lọ sinu Àgọ́ OLUWA, tí ó sì di ìwo pẹpẹ mú.

51 Wọ́n sọ fún Solomoni ọba pé ẹ̀rù rẹ ń ba Adonija ati pé ó wà níbi tí ó ti di ìwo pẹpẹ mú, tí ó sì wí pé, àfi kí Solomoni ọba fi ìbúra ṣèlérí pé kò ní pa òun.

52 Solomoni dáhùn pé, “Bí ó bá jẹ́ olóòótọ́, ẹnikẹ́ni kò ní fi ọwọ́ kan ẹyọ kan ninu irun orí rẹ̀, ṣugbọn bí ó bá hùwà ọ̀tẹ̀, yóo kú.”

53 Solomoni ọba bá ranṣẹ lọ mú Adonija wá láti ibi pẹpẹ. Adonija lọ siwaju ọba, ó sì wólẹ̀. Ọba sọ fún un pé kí ó máa lọ sí ilé rẹ̀.

Categories
ÀWỌN ỌBA KINNI

ÀWỌN ỌBA KINNI 2

Ìkìlọ̀ Ìkẹyìn Tí Dafidi ṣe fún Solomoni

1 Nígbà tí ó kù dẹ̀dẹ̀ kí Dafidi jáde láyé, ó pe Solomoni, ọmọ rẹ̀, ó sì kìlọ̀ fún un pé,

2 “Ó tó àkókò fún mi, láti lọ sí ibi tí àgbà ń rè. Mú ọkàn gírí kí o sì ṣe bí ọkunrin.

3 Ṣe gbogbo ohun tí OLUWA Ọlọrun rẹ pa láṣẹ fún ọ pé kí o ṣe, máa tẹ̀lé ọ̀nà rẹ̀, sì pa àwọn òfin ati ìlànà rẹ̀ mọ́, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ́ ọ sinu ìwé òfin Mose, kí gbogbo ohun tí o bá ń ṣe lè máa yọrí sí rere, níbikíbi tí o bá n lọ.

4 Bí o bá ń gbọ́ ti OLUWA, OLUWA yóo pa ìlérí tí ó ṣe nípa mi mọ́, pé arọmọdọmọ mi ni yóo máa jọba ní Israẹli níwọ̀n ìgbà tí wọ́n bá pa òfin òun mọ tọkàntọkàn, pẹlu òtítọ́ inú.

5 “Siwaju sí i, ranti ohun tí Joabu ọmọ Seruaya ṣe sí mi, tí ó pa àwọn ọ̀gágun Israẹli meji: Abineri ọmọ Neri ati Amasa ọmọ Jeteri. Ranti pé ní àkókò tí kò sí ogun ni ó pa wọ́n; tí ó fi gbẹ̀san ikú ẹni tí wọ́n pa ní àkókò ogun. Pípa tí ó pa àwọn aláìṣẹ̀ wọnyi, ọrùn mi ni ó pa wọ́n sí, ẹrù ẹ̀bi wọn sì wà lórí mi.

6 Ìwọ náà mọ ohun tí ó yẹ kí o ṣe gẹ́gẹ́ bí ọlọ́gbọ́n ọmọ, ṣugbọn o kò gbọdọ̀ jẹ́ kí ó fi ọwọ́ rọrí kú.

7 “Ṣugbọn òtítọ́ inú ni kí o máa fi bá àwọn ọmọ Basilai ará Gileadi lò. Jẹ́ kí wọ́n wà lára àwọn tí yóo máa bá ọ jẹun pọ̀, nítorí pé òótọ́ inú ni wọ́n fi wá pàdé mi ní àkókò tí mò ń sá lọ fún Absalomu, arakunrin rẹ.

8 “Bẹ́ẹ̀ náà sì ni Ṣimei ọmọ Gera ará Bahurimu láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini, èpè burúkú ni ó ń gbé mi ṣẹ́ lemọ́lemọ́ ní ọjọ́ tí mo lọ sí Mahanaimu. Ṣugbọn nígbà tí ó wá pàdé mi létí odò Jọdani, mo jẹ́jẹ̀ẹ́ fún un ní orúkọ OLUWA pé, n kò ní pa á.

9 Ṣugbọn o kò gbọdọ̀ jẹ́ kí ó lọ láìjìyà. Ìwọ náà mọ ohun tí ó yẹ kí o ṣe gẹ́gẹ́ bí ọlọ́gbọ́n ọmọ, o kò gbọdọ̀ jẹ́ kí ó fi ọwọ́ rọrí kú.”

Ikú Dafidi

10 Kò pẹ́ pupọ lẹ́yìn náà, Dafidi, ọba kú, wọ́n sì sin ín sí ìlú Dafidi.

11 Ogoji ọdún ni ó fi jọba Israẹli. Ó ṣe ọdún meje lórí oyè ní Heburoni, ó sì ṣe ọdún mẹtalelọgbọn ní Jerusalẹmu.

12 Solomoni gorí oyè lẹ́yìn ikú baba rẹ̀, ìjọba rẹ̀ sì fẹsẹ̀ múlẹ̀ gbọningbọnin.

Ikú Adonija

13 Ní ọjọ́ kan, Adonija ọmọ Hagiti, lọ sí ọ̀dọ̀ Batiṣeba, ìyá Solomoni. Batiṣeba bá bèèrè pé, “Ṣé alaafia ni o?”

Adonija dá a lóhùn pé, “Alaafia ni,

14 kinní kan ni mo fẹ́ bá ọ sọ.”

Batiṣeba bi í pé, “Kí ni?”

15 Ó bá dá Batiṣeba lóhùn pé, “Ṣé o mọ̀ pé èmi ni ó yẹ kí n jọba, ati pé gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ni wọ́n lérò pé èmi ni n óo jọba. Ṣugbọn kò rí bẹ́ẹ̀, arakunrin mi ló jọba, nítorí pé bẹ́ẹ̀ ni ó wu OLUWA.

16 Kinní kan ni mo wá fẹ́ tọrọ, jọ̀wọ́, má fi kinní ọ̀hún dù mí.”

Batiṣeba bá bi í pé, “Kí ni nǹkan náà?”

17 Ó bá dá Batiṣeba lóhùn, ó ní, “Jọ̀wọ́ bá mi bẹ Solomoni ọba, kí ó fún mi ní Abiṣagi, ará Ṣunemu, kí n fi ṣe aya. Mo mọ̀ pé kò ní kọ̀ sí ọ lẹ́nu.”

18 Batiṣeba bá dá a lóhùn pé, “Ó dára, n óo bá ọba sọ̀rọ̀.”

19 Batiṣeba bá lọ sọ́dọ̀ ọba láti jíṣẹ́ Adonija fún un. Bí ó ti wọlé, ọba dìde, ó tẹríba fún ìyá rẹ̀, ó sì kí i tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, ó bá tún jókòó sórí ìtẹ́ rẹ̀, ó ní kí wọ́n gbé ìjókòó kan wá, ìyá rẹ̀ sì jókòó ní apá ọ̀tún rẹ̀.

20 Batiṣeba wí fún Solomoni pé, “Nǹkan kékeré kan ni mo fẹ́ tọrọ lọ́wọ́ rẹ, jọ̀wọ́, má fi ohun náà dù mi.”

Ọba bèèrè pé, “Kí ni, ìyá mi?” Ó sì fi kún un pé òun kò ní fi dù ú.

21 Batiṣeba dá a lóhùn pé, “Fi Abiṣagi, ará Ṣunemu fún Adonija arakunrin rẹ, kí ó fi ṣe aya.”

22 Ọba bá bi ìyá rẹ̀ pé, “Kí ló dé tí o fi ní kí n fún un ní Abiṣagi nìkan? Ò bá kúkú ní kí n dìde fún un lórí ìtẹ́ tí mo wà yìí. Ṣebí òun ni ẹ̀gbọ́n mi, ẹ̀yìn rẹ̀ sì ni Abiatari alufaa ati Joabu ọmọ Seruaya wà.”

23 Solomoni bá búra lórúkọ OLUWA pé, kí Ọlọrun pa òun bí òun kò bá pa Adonija nítorí ọ̀rọ̀ yìí.

24 Ó ní, “Mo fi orúkọ OLUWA alààyè búra, ẹni tí ó gbé mi ka orí ìtẹ́ Dafidi baba mi tí ó fi ìdí mi múlẹ̀, tí ó mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ, tí ó sì fi ìjọba náà fún èmi ati arọmọdọmọ mi, lónìí olónìí ni Adonija yóo kú.”

25 Solomoni ọba bá pàṣẹ fún Bẹnaya, pé kí ó lọ pa Adonija, ó bá jáde, ó sì lọ pa á.

Wọ́n Lé Abiatari kúrò ní Ìlú, Wọ́n Sì Pa Joabu

26 Lẹ́yìn náà, Solomoni ọba sọ fún Abiatari alufaa, pé, “Wá pada lọ sí orí ilẹ̀ rẹ ní Anatoti, pípa ni ó yẹ kí n pa ọ́, ṣugbọn n kò ní pa ọ́ nisinsinyii, nítorí pé ìwọ ni o jẹ́ alákòóso fún gbígbé Àpótí Ẹ̀rí káàkiri nígbà tí o wà pẹlu Dafidi, baba mi, o sì bá baba mi pín ninu gbogbo ìṣòro rẹ̀.”

27 Solomoni bá yọ Abiatari kúrò ninu iṣẹ́ alufaa OLUWA tí ó ń ṣe, ó sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ tí OLUWA sọ ní Ṣilo ṣẹ, nípa Eli alufaa ati arọmọdọmọ rẹ̀.

28 Nígbà tí Joabu gbọ́ ohun tí ó ṣẹlẹ̀, ó sá lọ sinu Àgọ́ OLUWA, ó sì di ìwo pẹpẹ mú, nítorí pé lẹ́yìn Adonija ni ó ti wà tẹ́lẹ̀ rí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí lẹ́yìn Absalomu.

29 Nígbà tí Solomoni gbọ́ pé Joabu ti sá lọ sinu Àgọ́ OLUWA, ati pé ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ pẹpẹ, Solomoni rán Bẹnaya kí ó lọ pa á.

30 Bẹnaya bá lọ sinu Àgọ́ OLUWA, ó wí fún Joabu pé, “Ọba pàṣẹ pé kí o jáde.”

Ṣugbọn Joabu dá a lóhùn, ó ní, “Rárá, níhìn-ín ni n óo kú sí.”

Bẹnaya bá pada lọ sọ ohun tí Joabu wí fún ọba.

31 Ọba dá a lóhùn pé, “Ṣe bí Joabu ti ní kí o ṣe. Pa á, kí o sì sin ín. Nígbà náà ni ọrùn èmi, ati arọmọdọmọ Dafidi yóo tó mọ́ kúrò ninu ohun tí Joabu ṣe nígbà tí ó pa àwọn aláìṣẹ̀.

32 OLUWA yóo jẹ Joabu níyà fún àwọn eniyan tí ó pa láìjẹ́ pé Dafidi baba mí mọ ohunkohun nípa rẹ̀. Ó pa Abineri, ọmọ Neri, ọ̀gágun àwọn ọmọ ogun Israẹli ati Amasa, ọmọ Jeteri, ọ̀gágun àwọn ọmọ ogun Juda. Àwọn mejeeji tí ó pa láìṣẹ̀ yìí ṣe olóòótọ́ ju òun pàápàá lọ.

33 Ẹ̀jẹ̀ àwọn tí ó pa yóo wà lórí rẹ̀ ati lórí àwọn arọmọdọmọ rẹ̀ títí lae, ṣugbọn OLUWA yóo fún Dafidi ati àwọn arọmọdọmọ rẹ̀ ati ilé rẹ̀ ati ìjọba rẹ̀ ní alaafia títí lae.”

34 Bẹnaya ọmọ Jehoiada bá lọ sinu Àgọ́ OLUWA, ó pa Joabu, wọn sì sin ín sinu ilé rẹ̀ ninu aṣálẹ̀.

35 Ọba fi Bẹnaya jẹ balogun rẹ̀ dípò Joabu, ó sì fi Sadoku jẹ alufaa dípò Abiatari.

Ikú Ṣimei

36 Lẹ́yìn náà, ọba ranṣẹ pe Ṣimei, ó wí fún un pé, “Kọ́ ilé kan sí Jerusalẹmu níhìn-ín kí o sì máa gbé ibẹ̀. O kò gbọdọ̀ jáde lọ sí ibìkankan.

37 Ọjọ́ tí o bá jáde kọjá odò Kidironi, pípa ni n óo pa ọ́, ẹ̀jẹ̀ rẹ yóo sì wà lórí ara rẹ.”

38 Ṣimei dá a lóhùn, ó ní, “Gbogbo ohun tí o sọ ni ó dára, oluwa mi, bí o ti wí ni èmi iranṣẹ rẹ yóo sì ṣe.” Ṣimei sì wà ní Jerusalẹmu fún ìgbà pípẹ́.

39 Lẹ́yìn ọdún mẹta, àwọn ẹrú Ṣimei meji kan sá lọ sí ọ̀dọ̀ Akiṣi, ọmọ Maaka, ọba ìlú Gati. Nígbà tí Ṣimei gbọ́ pé àwọn ẹrú rẹ̀ yìí wà ní Gati,

40 ó di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ kan ní gàárì, ó sì tọ Akiṣi ọba lọ sí ìlú Gati láti lọ wá àwọn ẹrú rẹ̀. Ó rí wọn, ó sì mú àwọn mejeeji pada wá sí ilé.

41 Nígbà tí Solomoni gbọ́ pé Ṣimei ti kúrò ní Jerusalẹmu, ó ti lọ sí Gati, ó sì ti pada,

42 ó ranṣẹ pè é, ó bi í pé, “Ṣebí o búra fún mi ní orúkọ OLUWA pé o kò ní jáde kúrò ní Jerusalẹmu? Mo sì kìlọ̀ fún ọ pé, ní ọjọ́ tí o bá jáde, pípa ni n óo pa ọ́. O gbà bẹ́ẹ̀, o sì ṣèlérí fún mi pé o óo pa òfin náà mọ́.

43 Kí ló dé tí o kò mú ìlérí rẹ fún OLUWA ṣẹ, tí o sì rú òfin mi?”

44 Dájúdájú o mọ gbogbo ibi tí o ṣe sí Dafidi, baba mi; OLUWA yóo jẹ ọ́ níyà ohun tí o ṣe.

45 Ṣugbọn OLUWA yóo bukun mi, yóo sì fi ẹsẹ̀ ìjọba Dafidi múlẹ̀ títí lae.

46 Solomoni ọba bá pàṣẹ fún Bẹnaya, ọmọ Jehoiada, pé kí ó lọ pa Ṣimei; Bẹnaya bá jáde lọ, ó sì pa á. Lẹ́yìn náà ni gbogbo ìjọba Solomoni ọba wá wà ní ìkáwọ́ rẹ̀.

Categories
ÀWỌN ỌBA KINNI

ÀWỌN ỌBA KINNI 3

Solomoni Bẹ̀bẹ̀ fún Ọgbọ́n

1 Solomoni gbé ọmọ Farao, ọba Ijipti níyàwó, ó fi bá ọba Farao dá majẹmu àjọṣepọ̀ láàrin wọn. Solomoni mú iyawo náà wá sí ìlú Dafidi títí tí ó fi parí ààfin rẹ̀ ati ilé OLUWA tí ó ń kọ́, ati odi Jerusalẹmu tí ó ń mọ lọ́wọ́.

2 Oríṣìíríṣìí pẹpẹ ìrúbọ ni àwọn eniyan tẹ́ káàkiri, tí wọ́n sì ń rúbọ lórí wọn, nítorí wọn kò tí ì kọ́ ilé OLUWA nígbà náà.

3 Solomoni fẹ́ràn OLUWA, ó sì ń tẹ̀lé ìlànà Dafidi, baba rẹ̀, ṣugbọn òun náà a máa rúbọ, a sì máa sun turari lórí àwọn pẹpẹ ìrúbọ.

4 Ọba a máa lọ sí Gibeoni láti rúbọ, nítorí pé níbẹ̀ ni pẹpẹ tí ó lókìkí jùlọ nígbà náà wà. A máa fi ẹgbẹrun (1,000) ẹran rú ẹbọ sísun lórí pẹpẹ náà.

5 OLUWA fara han Solomoni ní ojú àlá ní òru ọjọ́ kan ní Gibeoni, ó sì bi í pé, “Kí ni o fẹ́ kí n fún ọ?”

6 Solomoni dá OLUWA lóhùn, ó ní: “O ti fi ìfẹ́ ńlá rẹ, tí kìí yẹ̀ hàn sí Dafidi, baba mi, iranṣẹ rẹ, nítorí pé ó bá ọ lò pẹlu òtítọ́, òdodo ati ọkàn dídúró ṣinṣin. O sì ti fi ìfẹ́ ńlá tí kì í yẹ̀ yìí hàn sí i, o fún un ní ọmọ tí ó jọba lẹ́yìn rẹ̀ lónìí.

7 Nisinsinyii, OLUWA Ọlọrun mi, ìwọ ni o jẹ́ kí èmi iranṣẹ rẹ gun orí oyè lẹ́yìn baba mi, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọde ni mí, n kò sì mọ̀ bí wọ́n ti ń ṣe àkóso.

8 O sì fi èmi iranṣẹ rẹ sí ààrin àwọn eniyan tí o ti yàn fún ara rẹ, àwọn tí wọ́n pọ̀, tóbẹ́ẹ̀ tí wọn kò lóǹkà.

9 Nítorí náà, OLUWA, fún èmi iranṣẹ rẹ ní ọgbọ́n láti darí àwọn eniyan rẹ, kí n lè mọ ìyàtọ̀ láàrin ire ati ibi, nítorí pé, bí kò bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, ta ni lè ṣe àkóso àwọn eniyan rẹ tí wọ́n pọ̀ báyìí?”

10 Inú OLUWA dùn fún ohun tí Solomoni bèèrè.

11 Ọlọrun sì dá a lóhùn, ó ní, “Nítorí pé ọgbọ́n láti mọ ohun tí ó dára ni o bèèrè, tí o kò bèèrè ẹ̀mí gígùn, tabi ọpọlọpọ ọrọ̀ fún ara rẹ, tabi ẹ̀mí àwọn ọ̀tá rẹ,

12 wò ó! N óo fún ọ ní ohun tí o bèèrè. Ọgbọ́n ati òye tí n óo fún ọ yóo tayọ ti gbogbo àwọn aṣiwaju rẹ, ati ti àwọn tí ń bọ̀ lẹ́yìn rẹ.

13 N óo fún ọ ní ohun tí o kò tilẹ̀ bèèrè. O óo ní ọrọ̀ ati ọlá tóbẹ́ẹ̀ tí kò ní sí ọba kan tí yóo dàbí rẹ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ.

14 Bí o bá ń gbọ́ tèmi, tí o sì ń pa gbogbo àwọn òfin, ati àwọn ìlànà mi mọ́, gẹ́gẹ́ bí Dafidi, baba rẹ ti ṣe, n óo fún ọ ní ẹ̀mí gígùn pẹlu.”

15 Nígbà tí Solomoni tají, ó rí i pé àlá ni òun ń lá, ó bá lọ sí Jerusalẹmu, ó lọ siwaju Àpótí Ẹ̀rí OLUWA, ó sì rú ẹbọ sísun ati ẹbọ alaafia sí OLUWA. Lẹ́yìn náà, ó se àsè ńlá fún gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀.

Solomoni Dá Ẹjọ́ Kan Tí Ó Ta Kókó

16 Ní ọjọ́ kan, àwọn aṣẹ́wó meji kan kó ara wọn wá siwaju Solomoni ọba.

17 Ọ̀kan ninu wọn ní, “Kabiyesi inú ilé kan náà ni èmi ati obinrin yìí ń gbé, ibẹ̀ ló sì wà nígbà tí mo fi bí ọmọkunrin kan.

18 Ọjọ́ kẹta tí mo bí ọmọ tèmi ni obinrin yìí náà bí ọmọkunrin kan. Àwa meji péré ni a wà ninu ilé, kò sí ẹnìkẹta pẹlu wa.

19 Ní alẹ́ ọjọ́ kan, ó sùn lé ọmọ tirẹ̀ mọ́lẹ̀, ọmọ tirẹ̀ bá kú.

20 Ó bá dìde ní ọ̀gànjọ́ òru, ó wá jí ọmọ tèmi gbé ní ẹ̀gbẹ́ mi nígbà tí mo sùn lọ, ó tẹ́ ẹ sí ọ̀dọ̀ ara rẹ̀, ó sì tẹ́ òkú ọmọ tirẹ̀ sọ́dọ̀ mi.

21 Nígbà tí mo jí ní ọjọ́ keji láti fún ọmọ ní oúnjẹ, mo rí i pé ó ti kú. Ṣugbọn nígbà tí mo yẹ̀ ẹ́ wò fínnífínní, mo rí i pé kì í ṣe ọmọ tèmi ni.”

22 Ṣugbọn obinrin keji dáhùn pé, “Rárá! Èmi ni mo ni ààyè ọmọ, òkú ọmọ ni tìrẹ.”

Ekinni náà tún dáhùn pé, “Irọ́ ni! Ìwọ ló ni òkú ọmọ, ààyè ọmọ ni tèmi.”

Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe bẹ̀rẹ̀ sí jiyàn níwájú ọba.

23 Nígbà náà ni Solomoni ọba dáhùn, ó ní, “Ekinni keji yín ń wí pé, òun kọ́ ni òun ni òkú ọmọ, ààyè ni tòun.”

24 Ọba bá ranṣẹ pé kí wọ́n mú idà kan wá. Nígbà tí wọ́n mú un dé,

25 ó pàṣẹ pé kí wọ́n la ààyè ọmọ sí meji, kí wọ́n sì fún àwọn obinrin mejeeji ní ìdajì, ìdajì.

26 Ọkàn ìyá tí ó ni ààyè ọmọ kò gbà á, nítorí ìfẹ́ tí ó ní sí ọmọ rẹ̀, ó wí fún ọba pé, “Kabiyesi, gbé ààyè ọmọ yìí fún ekeji mi, má pa á rárá.”

Ṣugbọn èyí ekeji dáhùn pé, “Rárá! Kò ní jẹ́ tèmi, kò sì ní jẹ́ tìrẹ. Jẹ́ kí wọ́n là á sí meji.”

27 Ọba dáhùn, ó ní, “Ẹ má pa ààyè ọmọ yìí rárá, ẹ gbé e fún obinrin àkọ́kọ́. Òun gan-an ni ìyá rẹ̀.”

28 Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli gbọ́ irú ìdájọ́ tí Solomoni ọba dá yìí, ó mú kí ó túbọ̀ níyì lójú wọn; nítorí wọ́n mọ̀ pé Ọlọrun ni ó fún un ní ọgbọ́n láti ṣe ìdájọ́ ní irú ọ̀nà ẹ̀tọ́ bẹ́ẹ̀.

Categories
ÀWỌN ỌBA KINNI

ÀWỌN ỌBA KINNI 4

Àwọn Òṣìṣẹ́ Solomoni

1 Solomoni jọba gbogbo ilẹ̀ Israẹli,

2 Orúkọ àwọn olórí ninu àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ nìwọ̀nyí: Asaraya, ọmọ Sadoku ni alufaa.

3 Elihorefi ati Ahija, meji ninu àwọn ọmọ Ṣiṣa ni akọ̀wé ní ààfin ọba. Jehoṣafati, ọmọ Ahiludi ni olùtọ́jú àwọn ìwé àkọsílẹ̀.

4 Bẹnaya, ọmọ Jehoiada, ni balogun. Sadoku ati Abiatari jẹ́ alufaa,

5 Asaraya, ọmọ Natani, ni olórí gbogbo àwọn òṣìṣẹ́. Sabudu, ọmọ Natani, ni alufaa ati olùdámọ̀ràn fún ọba.

6 Ahiṣari ni olùdarí gbogbo àwọn tí ń ṣiṣẹ́ ninu ààfin. Adoniramu ọmọ Abida ni olórí àwọn tí ń kó àwọn eniyan ṣiṣẹ́ tipátipá.

7 Solomoni yan àwọn mejila gẹ́gẹ́ bí alákòóso ní ilẹ̀ Israẹli. Àwọn ni wọ́n ń ṣe ètò àtikó oúnjẹ jọ ní agbègbè wọn, fún ìtọ́jú ọba ati gbogbo àwọn tí ń gbé ààfin ọba. Ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn á máa pèsè oúnjẹ fún oṣù kọ̀ọ̀kan ninu ọdún kọ̀ọ̀kan.

8 Orúkọ àwọn alákòóso mejeejila ati agbègbè tí olukuluku wọn ń mójú tó nìwọ̀nyí: Benhuri ní ń ṣe àkóso agbègbè olókè Efuraimu;

9 Bẹndekeri ni alákòóso fún ìlú Makasi, ati Ṣaalibimu, ìlú Beti Ṣemeṣi, Eloni, ati Beti Hanani.

10 Benhesedi ní Aruboti ni alákòóso fún ìlú Aruboti, ati Soko, ati gbogbo agbègbè Heferi.

11 Bẹnabinadabu, ọkọ Tafati, ọmọ Solomoni, ni alákòóso gbogbo agbègbè Nafati-dori.

12 Baana, ọmọ Ahiludi, ni alákòóso ìlú Taanaki, ati ti Megido, ati gbogbo agbègbè Beti Ṣeani, lẹ́bàá ìlú Saretani, ní ìhà gúsù Jesireeli ati Beti Ṣeani; títí dé ìlú Abeli Mehola títí dé òdìkejì Jokimeamu.

13 Bẹngeberi ni alákòóso ìlú Ramoti Gileadi, (ati àwọn ìletò Jairi, ọmọ Manase, tí ó wà ní ilẹ̀ Gileadi, ati agbègbè Arigobu, ní ilẹ̀ Baṣani. Gbogbo wọn jẹ́ ọgọta ìlú ńláńlá tí wọn mọ odi yíká, bàbà ni wọ́n sì fi ṣe ọ̀pá ìdábùú ìlẹ̀kùn ẹnubodè wọn.)

14 Ahinadabu, ọmọ Ido ni alákòóso agbègbè Mahanaimu.

15 Ahimaasi, (ọkọ Basemati, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Solomoni), ni alákòóso Nafutali.

16 Baana, ọmọ Huṣai, ni alákòóso agbègbè Aṣeri, ati Bealoti.

17 Jehoṣafati, ọmọ Parua, ni alákòóso agbègbè Isakari.

18 Ṣimei, ọmọ Ela, ni alákòóso agbègbè Bẹnjamini.

19 Geberi, ọmọ Uri, ni alákòóso agbègbè Gileadi, níbi tí Sihoni ọba àwọn ará Amori ati Ogu ọba Baṣani ti jọba tẹ́lẹ̀ rí.

Lẹ́yìn àwọn alákòóso mejeejila wọnyi, alákòóso àgbà kan tún wà fún gbogbo ilẹ̀ Juda.

Ìjọba Solomoni Ní Ìtẹ̀síwájú ati Alaafia

20 Àwọn ọmọ Juda ati àwọn ọmọ Israẹli pọ̀ bíi yanrìn inú òkun, wọ́n ń rí jẹ, wọ́n ń rí mu, wọ́n sì láyọ̀.

21 Solomoni jọba lórí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè, láti odò Yufurate títí dé ilẹ̀ Filistia, títí dé ààlà ilẹ̀ àwọn ará Ijipti. Wọ́n ń san ìṣákọ́lẹ̀ fún un, wọ́n sì ń sìn ín ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.

22 Àwọn nǹkan tí Solomoni ń lò fún ìtọ́jú oúnjẹ ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan nìwọ̀nyí: Ọgbọ̀n òṣùnwọ̀n ìyẹ̀fun tí ó kúnná dáradára, ati ọgọta òṣùnwọ̀n ọkà tí wọ́n lọ̀;

23 àbọ́pa mààlúù mẹ́wàá, ogún mààlúù tí wọn ń dà ninu pápá, ati ọgọrun-un aguntan; láìka àgbọ̀nrín, egbin, ìgalà, ati oríṣìíríṣìí ẹyẹ àbọ́pa.

24 Solomoni jọba lórí gbogbo ilẹ̀ tí ó wà ní apá ìwọ̀ oòrùn odò Yufurate, láti ìlú Tifisa, títí dé ìlú Gasa, ati lórí gbogbo àwọn ọba tí wọ́n wà ní apá ìwọ̀ oòrùn odò Yufurate; alaafia sì wà láàrin òun ati àwọn agbègbè tí ó wà ní àyíká rẹ̀.

25 Ní gbogbo àkókò Solomoni, gbogbo àwọn ọmọ Juda ati àwọn ọmọ Israẹli wà ní alaafia láti ìlú Dani títí dé Beeriṣeba. Ìdílé kọ̀ọ̀kan ní ọgbà àjàrà ati àwọn igi ọ̀pọ̀tọ́ tirẹ̀.

26 Ọ̀kẹ́ meji (40,000) ni ilé tí Solomoni kọ́ fún àwọn ẹṣin tí ń fa àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, ó sì ní ẹgbaafa (12,000) eniyan tí ń gun ẹṣin.

27 Alákòóso kọ̀ọ̀kan níí máa tọ́jú nǹkan jíjẹ tí Solomoni ọba ń lò fún ara rẹ̀ ati fún gbogbo àwọn tí ń jẹun ní ààfin rẹ̀; alákòóso kọ̀ọ̀kan sì ní oṣù tí ó gbọdọ̀ pèsè nǹkan jíjẹ, láìjẹ́ kí ohunkohun dín ninu ohun tí ọba nílò.

28 Wọn a sì máa mú ọkà baali ati koríko wá fún àwọn ẹṣin tí ń wa kẹ̀kẹ́ ogun ati àwọn ẹṣin tí wọ́n fi ń ṣiṣẹ́. Olukuluku a máa mú ohun tí wọ́n bù fún un wá sí ibi tí wọ́n ti nílò rẹ̀.

29 Ọgbọ́n ati òye tí Ọlọrun fún Solomoni kọjá sísọ, ìmọ̀ rẹ̀ sì kọjá ìwọ̀n.

30 Solomoni gbọ́n ju àwọn amòye ìhà ìlà oòrùn ati ti Ijipti lọ.

31 Òun ni ó gbọ́n jùlọ ní gbogbo ayé. Ó gbọ́n ju Etani ará Ẹsira lọ, ati Hemani, ati Kakoli, ati Dada, àwọn ọmọ Maholi. Òkìkí rẹ̀ sì kàn káàkiri gbogbo agbègbè tí ó yí i ká.

32 Ẹgbẹẹdogun (3,000) ni òwe tí òun nìkan pa, orin tí òun nìkan kọ sì jẹ́ marunlelẹgbẹrun.

33 Ó sọ nípa igi, ó bẹ̀rẹ̀ láti orí igi kedari ti ilẹ̀ Lẹbanoni, títí kan Hisopu tí ó ń hù lára ògiri. Ó sọ nípa àwọn ẹranko, ati àwọn ẹyẹ, àwọn ohun tí ń fi àyà fà ati àwọn ẹja.

34 Àwọn eniyan sì ń wá láti oniruuru orílẹ̀ èdè, ati láti ọ̀dọ̀ àwọn ọba ní gbogbo ayé, tí wọ́n ti gbúròó nípa ọgbọ́n rẹ̀, wọn á wá tẹ́tí sí ọgbọ́n rẹ̀.

Categories
ÀWỌN ỌBA KINNI

ÀWỌN ỌBA KINNI 5

Solomoni Palẹ̀mọ́ láti Kọ́ Tẹmpili

1 Nígbà tí Hiramu, ọba Tire, gbọ́ pé Solomoni ni ó gun orí oyè lẹ́yìn baba rẹ̀, ó rán oníṣẹ́ sí i; nítorí ọ̀rẹ́ ni òun ati Dafidi, wọ́n sì fẹ́ràn ara wọn.

2 Solomoni náà ranṣẹ pada sí Hiramu,

3 ó ní, “Ìwọ náà mọ̀ pé Dafidi, baba mi, kò lè kọ́ ilé ìsìn fún OLUWA Ọlọrun rẹ̀ nítorí gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀ ni ó fi bá àwọn ọ̀tá rẹ̀ tí wọ́n yí i ká jagun, títí tí OLUWA fi fún un ní ìṣẹ́gun lórí wọn.

4 Ṣugbọn nisinsinyii, OLUWA Ọlọrun mi ti fún mi ní alaafia ní gbogbo agbègbè tí ó yí mi ká. N kò ní ọ̀tá kankan rárá, bẹ́ẹ̀ ni kò sí àjálù.

5 Nisinsinyii, mo ti ṣe ìpinnu láti kọ́ ilé fún OLUWA Ọlọrun mi, gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ̀ sí Dafidi, baba mi, pé ọmọ rẹ̀, tí yóo gun orí oyè lẹ́yìn rẹ̀, ni yóo kọ́ ilé ìsìn fún òun.

6 Nítorí náà, pàṣẹ fún àwọn iranṣẹ rẹ, kí wọ́n bá mi gé igi kedari ní Lẹbanoni. Àwọn iranṣẹ mi yóo bá wọn ṣiṣẹ́ pọ̀, n óo sì san iyekíye tí o bá bèèrè fún owó iṣẹ́ wọn. Gẹ́gẹ́ bí ìwọ náà ti mọ̀, àwọn iranṣẹ mi kò mọ̀ bí a tií gé igi ìkọ́lé bí àwọn ará Sidoni.”

7 Inú ọba Hiramu dùn pupọ nígbà tí wọ́n jíṣẹ́ Solomoni fún un. Ó ní, “Ẹni ìyìn ni OLUWA lónìí, nítorí pé ó fún Dafidi ní ọlọ́gbọ́n ọmọ, láti jọba lórí orílẹ̀-èdè ńlá yìí.”

8 Ó ranṣẹ pada sí Solomoni, ó ní, “Mo gbọ́ iṣẹ́ tí o rán sí mi, n óo sì ṣe ohun tí o ní kí n ṣe fún ọ nípa igi kedari ati igi sipirẹsi.

9 Àwọn iranṣẹ mi yóo gé igi náà ní Lẹbanoni, wọn yóo kó wọn wá sí etí òkun. Wọn óo dì wọ́n ní ìdì kọ̀ọ̀kan kí wọ́n lè tù wọ́n gba ojú òkun lọ sí ibikíbi tí o bá fẹ́. Wọn óo tú wọn kalẹ̀ níbẹ̀, wọn óo sì kó wọn fún àwọn iranṣẹ rẹ. Ohun tí mo fẹ́ kí o mójútó ni oúnjẹ tí èmi ati ìdílé mi óo máa jẹ.”

10 Bẹ́ẹ̀ ni Hiramu ṣe tọ́jú gbogbo igi kedari ati igi sipirẹsi tí Solomoni nílò fún un.

11 Ní ọdọọdún, Solomoni a máa fún Hiramu ní ọ̀kẹ́ kan (20,000) òṣùnwọ̀n kori ọkà, ati ọ̀kẹ́ kan (20,000) òṣùnwọ̀n kori òróró dáradára fún ìtọ́jú oúnjẹ fún Hiramu ati àwọn eniyan rẹ̀.

12 OLUWA fún Solomoni ní ọgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ̀, alaafia sì wà láàrin òun ati Hiramu, àwọn mejeeji sì bá ara wọn dá majẹmu.

13 Solomoni ọba ṣa ẹgbaa mẹẹdogun (30,000) eniyan jọ lára àwọn ọmọ Israẹli, láti ṣe iṣẹ́ tipátipá.

14 Ó fi Adoniramu ṣe alabojuto wọn. Ó pín wọn sí ọ̀nà mẹta: ẹgbaarun (10,000) ọkunrin ní ìpín kọ̀ọ̀kan. Ìpín kọ̀ọ̀kan a máa ṣiṣẹ́ fún oṣù kan ní Lẹbanoni, wọn á sì pada sílé fún oṣù meji.

15 Solomoni sì tún ní ọ̀kẹ́ mẹrin (80,000) ọkunrin tí ń fọ́ òkúta ní agbègbè olókè; ati ọ̀kẹ́ mẹta ó lé ẹgbaarun (70,000) ọkunrin tí ń ru òkúta tí wọ́n bá fọ́.

16 Ó yan ẹẹdẹgbaaji ó lé ọọdunrun (3,300) ọkunrin, láti máa bojútó iṣẹ́ àwọn òṣìṣẹ́.

17 Gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Solomoni ọba, wọ́n fọ́ òkúta ńláńlá, wọ́n sì gbẹ́ wọn fún mímọ ìpìlẹ̀ ilé OLUWA náà.

18 Àwọn òṣìṣẹ́ Solomoni ati ti Hiramu, ati àwọn ọkunrin mìíràn láti ìlú Gebali ni wọ́n gbẹ́ òkúta, tí wọ́n sì la igi fún kíkọ́ ilé OLUWA.

Categories
ÀWỌN ỌBA KINNI

ÀWỌN ỌBA KINNI 6

Solomoni Kọ́ Tẹmpili

1 Nígbà tí ó di ọrinlenirinwo (480) ọdún tí àwọn ọmọ Israẹli kúrò ní ilẹ̀ Ijipti, ní ọdún kẹrin tí Solomoni gun orí oyè ní Israẹli, ní oṣù Sifi, tíí ṣe oṣù keji ọdún náà, ni ó bẹ̀rẹ̀ kíkọ́ ilé OLUWA.

2 Gígùn ilé tí Solomoni kọ́ fún OLUWA jẹ́ ọgọta igbọnwọ, ìbú rẹ̀ jẹ́ ogún igbọnwọ, gíga rẹ̀ sì jẹ́ ọgbọ̀n igbọnwọ.

3 Yàrá àbáwọlé ilé ìsìn náà gùn ní ogún igbọnwọ, gígùn rẹ̀ ṣe déédé pẹlu ìbú rẹ̀, ó sì jìn sí ìsàlẹ̀ ní igbọnwọ mẹ́wàá níwájú.

4 Ògiri ilé ìsìn náà ní àwọn fèrèsé tí wọ́n fẹ̀ ninu ju bí wọ́n ti fẹ̀ lóde lọ.

5 Wọ́n kọ́ ilé alágbèékà mẹta mọ́ ara ògiri ilé ìsìn náà yípo lọ́wọ́ òde, ati gbọ̀ngàn ti òde, ati ibi mímọ́ ti inú; wọ́n sì kọ́ yàrá ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ sí i yípo. Gíga àgbékà kọ̀ọ̀kan ilé náà jẹ́ igbọnwọ marun-un;

6 ilé ti ìsàlẹ̀ fẹ̀ ní igbọnwọ marun-un; àgbékà ti ààrin fẹ̀ ní igbọnwọ mẹfa, àgbékà ti òkè patapata fẹ̀ ní igbọnwọ meje. Ògiri àgbékà tí ó wà ní òkè patapata kò nípọn tó ti èyí tí ó wà ní ààrin, ti ààrin kò sì nípọn tó ti èyí tí ó wà ní ìsàlẹ̀ patapata; tí ó fi jẹ́ pé àwọn yàrá náà lè jókòó lórí ògiri láìfi òpó gbé wọn ró.

7 Níbi tí wọ́n ti ń fọ́ òkúta ni wọ́n ti gbẹ́ gbogbo òkúta tí wọ́n fi kọ́ ilé ìsìn náà, wọn kò lo òòlù, tabi àáké, tabi ohun èlò irin kankan ninu tẹmpili náà nígbà tí wọ́n ti ń kọ́ ọ lọ.

8 Ninu ilé alágbèékà mẹta tí wọ́n kọ́ mọ́ ara ilé ìsìn náà, ẹnu ọ̀nà ilé tí ó wà ní ìsàlẹ̀ patapata wà ní apá gúsù ilé ìsìn náà, ó ní àtẹ̀gùn tí ó lọ sí àgbékà keji, àgbékà keji sì ní àtẹ̀gùn tí ó lọ sí àgbékà kẹta.

9 Bẹ́ẹ̀ ni Solomoni ọba ṣe kọ́ ilé ìsìn náà parí, ó sì fi ọ̀pá àjà ati pákó igi kedari ṣe àjà rẹ̀.

10 Ara ògiri ilé ìsìn náà níta ni wọ́n kọ́ ilé alágbèékà mẹta yìí mọ́, àgbékà kọ̀ọ̀kan ga ní igbọnwọ marun-un, wọ́n sì fi pákó igi kedari so wọ́n pọ̀ mọ́ ara ilé ìsìn náà.

11 OLUWA wí fún Solomoni ọba pé,

12 “Ní ti ilé ìsìn tí ò ń kọ́ yìí, bí o bá pa gbogbo òfin mi mọ́, tí o sì tẹ̀lé ìlànà mi, n óo ṣe gbogbo ohun tí mo ṣèlérí fún Dafidi, baba rẹ, fún ọ.

13 N óo máa gbé ààrin àwọn ọmọ Israẹli, n kò sì ní kọ eniyan mi sílẹ̀ laelae.”

14 Bẹ́ẹ̀ ni Solomoni ṣe parí kíkọ́ ilé ìsìn náà.

Àrà Tí Solomoni Dá sinu Tẹmpili náà

15 Pákó igi kedari ni ó fi bo ara ògiri ilé náà ninu, láti òkè dé ilẹ̀. Pákó igi sipirẹsi ni wọ́n sì fi tẹ́ gbogbo ilẹ̀ rẹ̀.

16 Wọ́n kọ́ yàrá kan tí wọn ń pè ní Ibi-Mímọ́-Jùlọ, sí ọwọ́ ẹ̀yìn ilé ìsìn náà. Gígùn rẹ̀ jẹ́ ogún igbọnwọ, pákó kedari ni wọn fi gé e láti òkè dé ilẹ̀.

17 Gbọ̀ngàn tí ó wà níwájú Ibi-Mímọ́-Jùlọ yìí gùn ní ogoji igbọnwọ.

18 Wọ́n gbẹ́ àwòrán agbè ati òdòdó, wọ́n fi ṣe ọ̀ṣọ́ sára igi kedari tí wọ́n fi bo ògiri gbọ̀ngàn náà, òkúta tí wọ́n fi mọ ògiri ilé náà kò sì hàn síta rárá.

19 Wọ́n kọ́ ibi mímọ́ kan sí ọwọ́ ẹ̀yìn ilé ìsìn náà, inú ibi mímọ́ yìí ni wọ́n gbé Àpótí Ẹ̀rí OLUWA sí.

20 Gígùn ibi mímọ́ ti inú yìí jẹ́ ogún igbọnwọ, ó fẹ̀ ní ogún igbọnwọ, gíga rẹ̀ náà sì jẹ́ ogún igbọnwọ. Ojúlówó wúrà ni wọ́n fi bo gbogbo ibi mímọ́ náà; wọ́n sì fi pákó igi kedari ṣe pẹpẹ kan sibẹ.

21 Ojúlówó wúrà ni Solomoni fi bo gbogbo inú ilé ìsìn náà, wọ́n sì so ẹ̀wọ̀n kan, ó fi dábùú ẹnu ọ̀nà ibi mímọ́ ti inú, ó sì yọ́ wúrà bò ó.

22 Gbogbo inú ilé ìsìn náà patapata ni wọ́n fi wúrà bò, ati pẹpẹ tí ó wà ninu Ibi-Mímọ́-Jùlọ.

23 Wọ́n fi igi olifi gbẹ́ ẹ̀dá abìyẹ́ meji tí wọn ń pè ní Kerubu, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ga ní igbọnwọ mẹ́wàá, wọ́n kó wọn sinu Ibi-Mímọ́-Jùlọ náà.

24 Ìyẹ́ kọ̀ọ̀kan àwọn Kerubu mejeeji gùn ní igbọnwọ marun-un, tí ó fi jẹ́ pé láti ṣóńṣó ìyẹ́ kinni Kerubu kọ̀ọ̀kan dé ṣóńṣo ìyẹ́ rẹ̀ keji jẹ́ igbọnwọ mẹ́wàá.

25 Gígùn ìyẹ́ mejeeji Kerubu keji náà jẹ́ igbọnwọ mẹ́wàá. Bákan náà ni àwọn Kerubu mejeeji yìí rí, bákan náà sì ni títóbi wọn.

26 Ekinni keji wọn ga ní igbọnwọ mẹ́wàá.

27 Ó gbé wọn kalẹ̀ sí ẹ̀gbẹ́ ara wọn ninu Ibi-Mímọ́-Jùlọ. Àwọn mejeeji na ìyẹ́ wọn tí ó fi jẹ́ pé ọ̀kan ninu àwọn ìyẹ́ Kerubu kinni kan ògiri yàrá ní ẹ̀gbẹ́ kan, ọ̀kan ninu àwọn ìyẹ́ Kerubu keji sì kan ògiri yàrá ní ẹ̀gbẹ́ keji. Ìyẹ́ keji Kerubu kinni ati ìyẹ́ kinni Kerubu keji sì kan ara wọn ní ààrin yàrá náà.

28 Wúrà ni wọ́n yọ́ bo àwọn Kerubu náà.

29 Wọ́n gbẹ́ àwòrán igi ọ̀pẹ, ati ti òdòdó, ati ti Kerubu yípo ara ògiri yàrá tí ó wà ninu ati èyí tí ó wà lóde;

30 wọ́n sì yọ́ wúrà bo ilẹ̀ àwọn yàrá náà.

31 Wọ́n ri ìlẹ̀kùn meji, alápapọ̀, tí wọ́n fi igi olifi ṣe, mọ́ ẹnu ọ̀nà Ibi-Mímọ́-Jùlọ. Àtẹ́rígbà ìlẹ̀kùn náà rí ṣóńṣó ní ààrin,

32 wọ́n gbẹ́ igi ọ̀pẹ, ati òdòdó, ati kerubu sí ara àwọn ìlẹ̀kùn náà; wọ́n sì yọ́ wúrà bò wọ́n patapata: ati igi ọ̀pẹ, ati òdòdó, ati àwọn Kerubu náà.

33 Wọ́n fi igi olifi ṣe férémù ìlẹ̀kùn onígun mẹrin, wọ́n rì í mọ́ ẹnu ọ̀nà àbáwọ gbọ̀ngàn ńlá.

34 Wọn fi igi sipirẹsi ṣe ìlẹ̀kùn meji, ekinni keji ní awẹ́ meji, awẹ́ ekinni keji sì ṣe é pàdé mọ́ ara wọn.

35 Wọ́n gbẹ́ igi ọ̀pẹ, ati òdòdó, ati àwọn kerubu sí ara àwọn ìlẹ̀kùn náà, wọ́n sì fi wúrà bo gbogbo wọn.

36 Bí wọ́n ṣe mọ ògiri àgbàlá inú ilé ìsìn náà ni pé, bí wọ́n bá mọ ìlè òkúta mẹta wọn a mọ ìlè igi kedari kan.

37 Ninu oṣù Sifi, ní ọdún kẹrin ìjọba Solomoni, ni wọ́n fi ìpìlẹ̀ ilé ìsìn náà sọlẹ̀.

38 Ninu oṣù Bulu, ní ọdún kọkanla ìjọba Solomoni ni wọ́n kọ́ ilé ìsìn náà parí patapata, ó sì rí bí wọ́n ti ṣètò pé kó rí gẹ́lẹ́. Ọdún meje ni ó gba Solomoni láti parí rẹ̀.

Categories
ÀWỌN ỌBA KINNI

ÀWỌN ỌBA KINNI 7

Ààfin Solomoni

1 Ọdún mẹtala ni Solomoni fi parí kíkọ́ ilé ti ara rẹ̀.

2 Ọ̀kan ninu àwọn ilé tí ó kọ́ sí ààfin náà ni Ilé Igbó Lẹbanoni. Ilé náà gùn ní ọgọrun-un (100) igbọnwọ, fífẹ̀ rẹ̀ jẹ́ aadọta igbọnwọ, ó sì ga ní ọgbọ̀n igbọnwọ. Orí òpó igi kedari, tí wọ́n na ọ̀pá àjà igi kedari lé, ni wọ́n kọ́ ọ lé.

3 Wọ́n to àwọn òpó, tí wọ́n kọ́ ilé yìí lé lórí, ní ìlà mẹta. Òpó mẹẹdogun mẹẹdogun wà ní ìlà kọ̀ọ̀kan. Wọ́n wá na ìtì igi kedari lé àwọn òpó náà lórí.

4 Ìlà mẹta mẹta ni wọ́n to fèrèsé sí, àwọn fèrèsé ilé náà kọjú sí ara wọn ní àgbékà mẹta.

5 Onígun mẹrin ni wọ́n ṣe férémù tí wọ́n fi ṣe àwọn ẹnu ọ̀nà ati fèrèsé ilé náà, wọ́n to àwọn fèrèsé ní ìlà mẹta mẹta ninu ògiri, ni àgbékà àgbékà, lẹ́gbẹ̀ẹ́ kinni keji ilé náà; wọ́n dojú kọ ara wọn.

6 Ó kọ́ gbọ̀ngàn kan tí ó sọ ní gbọ̀ngàn Olópòó. Gígùn rẹ̀ jẹ́ aadọta igbọnwọ, ìbú rẹ̀ sì jẹ́ ọgbọ̀n igbọnwọ. Ó ní ìloro kan tí wọ́n kọ́ sórí òpó; wọ́n ta nǹkan bò ó lórí.

7 Ó kọ́ gbọ̀ngàn ìtẹ́ kan, níbi tí yóo ti máa dájọ́; igi kedari ni wọ́n fi ṣe ara ògiri rẹ̀ láti òkè délẹ̀.

8 Ó kọ́ ilé tí òun alára óo máa gbé sí àgbàlá tí ó wà lẹ́yìn gbọ̀ngàn bí ó ti kọ́ àwọn ilé yòókù; ó sì kọ́ irú gbọ̀ngàn yìí gan-an fún ọmọ ọba Farao tí ó gbé ní iyawo.

9 Òkúta olówó ńlá, tí wọ́n fi ayùn gé tinú-tẹ̀yìn, ni wọ́n fi kọ́ gbogbo ilé ati àgbàlá rẹ̀, láti ìpìlẹ̀ títí dé òrùlé rẹ̀, ati láti àgbàlá ilé OLUWA títí dé àgbàlá ńlá náà.

10 Òkúta ńláńlá, olówó ńláńlá, onígbọ̀nwọ́ mẹjọ ati onígbọ̀nwọ́ mẹ́wàá ni wọ́n fi ṣe ìpìlẹ̀ ilé náà.

11 Òkúta olówó ńlá tí a wọ̀n kí á tó gé e, ati igi kedari, ni wọ́n fi ṣe ògiri rẹ̀.

12 Ìlè mẹta mẹta òkúta gbígbẹ́ tí a fi ìlé kan igi kedari là láàrin, ni wọ́n fi kọ́ àgbàlá ńlá náà yípo. Bẹ́ẹ̀ náà sì ni àgbàlá ti inú ilé OLUWA ati yàrá àbáwọlé.

Iṣẹ́ Huramu

13 Solomoni ọba ranṣẹ pé kí wọ́n lọ mú Huramu wá láti Tire,

14 ará Tire ni baba rẹ̀, ṣugbọn opó ọmọ ẹ̀yà Nafutali kan ni ìyá rẹ̀. Baba rẹ̀ ti jáde láyé, ṣugbọn nígbà ayé rẹ̀, òun náà mọ iṣẹ́ àgbẹ̀dẹ bàbà dáradára. Huramu gbọ́n, ó lóye, ó sì mọ bí a tíí fi idẹ ṣe oríṣìíríṣìí iṣẹ́ ọnà. Ó tọ Solomoni lọ, ó sì bá a ṣe gbogbo iṣẹ́ rẹ̀.

Òpó Bàbà Meji

15 Ó fi bàbà ṣe òpó meji; gíga ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ igbọnwọ mejidinlogun, àyíká rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mejila, ó ní ihò ninu, nínípọn rẹ̀ sì jẹ́ ìka mẹrin. Bákan náà ni òpó keji.

16 Ó sì rọ ọpọ́n bàbà meji, ó gbé wọn ka orí àwọn òpó náà. Gíga àwọn ọpọ́n náà jẹ́ igbọnwọ marun-un marun-un.

17 Ó fi irin hun àwọ̀n meji fún àwọn ọpọ́n orí mejeeji tí wọ́n wà lórí àwọn òpó náà, àwọ̀n kọ̀ọ̀kan fún ọpọ́n orí òpó kọ̀ọ̀kan.

18 Bákan náà ni ó ṣe èso pomegiranate ní ìlà meji, ó fi wọ́n yí iṣẹ́ ọnà àwọ̀n náà po, ó sì fi dárà sí ọpọ́n tí ó wà lórí òpó. Bákan náà ni ó ṣe sí ọpọ́n orí òpó keji.

19 Wọ́n ṣe ọpọ́n orí òpó inú yàrá àbáwọlé náà bí ìtànná lílì, ó ga ní igbọnwọ mẹrin.

20 Ọpọ́n kọ̀ọ̀kan wà lórí òpó mejeeji, lórí ibi tí ó yọ jáde tí ó rí bìrìkìtì lára àwọn òpó, lẹ́gbẹ̀ẹ́ iṣẹ́ ọnà náà. Igba èso pomegiranate ni wọ́n fi yí àwọn òpó náà ká ní ọ̀nà meji. Bẹ́ẹ̀ ló ṣe sí òpó keji pẹlu.

21 Ó ri àwọn òpó mejeeji yìí sí àbáwọ Tẹmpili, wọ́n ri ọ̀kan sí ìhà gúsù, wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Jakini; wọ́n ri ekeji sí apá àríwá, wọ́n sì pè é ní Boasi.

22 Iṣẹ́ ọnà ìtànná lílì ni wọ́n ṣe sára àwọn òpó náà.

Bẹ́ẹ̀ ni iṣẹ́ ṣe parí lórí àwọn òpó náà.

Agbada Bàbà

23 Ó ṣe agbada omi rìbìtì kan. Jíjìn rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ marun-un ààbọ̀, fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mẹ́wàá. Àyíká rẹ̀ sì jẹ́ ọgbọ̀n igbọnwọ.

24 Wọ́n fi idẹ ṣe ọpọlọpọ agbè, wọ́n tò wọ́n ní ìlà meji sí etí agbada omi náà. Láti ilẹ̀ ni wọ́n ti ṣe àwọn agbè yìí ní àṣepọ̀ mọ́ agbada omi náà.

25 Wọ́n gbé agbada yìí ka orí akọ mààlúù mejila, tí wọ́n fi bàbà ṣe. Mẹta ninu àwọn mààlúù náà dojú kọ apá ìhà àríwá, àwọn mẹta dojú kọ apá ìwọ̀ oòrùn, àwọn mẹta dojú kọ apá gúsù, àwọn mẹta sì dojú kọ apá ìlà oòrùn.

26 Agbada náà nípọn ní ìwọ̀n ìbú àtẹ́lẹwọ́ kan. Etí rẹ̀ dàbí etí ife omi, ó tẹ̀ ní àtẹ̀sóde bí ìsàlẹ̀ òdòdó lílì. Agbada náà lè gbà tó ẹgbaa (2,000) galọọnu omi.

Ọkọ̀ Bàbà

27 Huramu tún fi bàbà ṣe ìtẹ́lẹ̀ mẹ́wàá, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn gùn ní igbọnwọ mẹrin, wọ́n fẹ̀ ní igbọnwọ mẹrin, wọ́n sì ga ní igbọnwọ mẹta.

28 Báyìí ni wọ́n ṣe mọ àwọn ìtẹ́lẹ̀ náà: wọ́n ní ìtẹ́dìí, àwọn ìtẹ́dìí yìí sì ní igun mẹrin mẹrin,

29 lórí àwọn ìtẹ́dìí yìí ni ó ya àwòrán àwọn kinniun, mààlúù ati ti kerubu sí. Wọ́n ṣe àwọn ọnà róbótó róbótó kan báyìí sí òkè àwọn kinniun ati akọ mààlúù náà ati sí ìsàlẹ̀ wọn.

30 Olukuluku ìtẹ́lẹ̀ yìí ni ó ní àgbá kẹ̀kẹ́ idẹ mẹrin, igun mẹrẹẹrin rẹ̀ sì ní ìtẹ́lẹ̀, lábẹ́ agbada náà ni àwọn ìtẹ́lẹ̀ tí a rọ wà. A ṣe ọ̀ṣọ́ sí gbogbo igun ìtẹ́lẹ̀ náà,

31 òkè agbada náà dàbí adé tí a yọ sókè ní igbọnwọ kan, wọ́n sì ṣe iṣẹ́ ọnà aláràbarà yí etí rẹ̀ po.

32 Àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ mẹrẹẹrin wà lábẹ́ àwọn ìtẹ́dìí yìí, àṣepọ̀ mọ́ ìtẹ́lẹ̀ ni wọ́n ṣe àwọn ọ̀pá inú àgbá kẹ̀kẹ́ náà. Gíga àgbá kẹ̀kẹ́ kọ̀ọ̀kan sì jẹ́ igbọnwọ kan ààbọ̀.

33 Ó ṣe àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ yìí bíi ti kẹ̀kẹ́ ogun, dídà ni wọ́n dà á ati irin tí àgbá náà fi ń yí, ati riimu wọn, ati sipoku ati họọbu wọn.

34 Ìtẹ́lẹ̀ mẹrin mẹrin ló wà ní orígun mẹrẹẹrin àwọn ìtẹ́dìí náà, ẹyọ kan náà ni wọ́n ṣe àwọn ìtẹ́lẹ̀ pẹlu ìtẹ́dìí yìí.

35 A mọ ìgbátí yíká òkè àwọn ìtẹ́lẹ̀ náà, tí ó ga sókè ní ààbọ̀ igbọnwọ, ìgbátí yìí wà ní téńté orí àwọn ìtẹ́lẹ̀ náà. Àṣepọ̀ ni wọ́n ṣe òun ati ìtẹ́dìí rẹ̀.

36 Ó ya àwòrán àwọn kerubu, ati kinniun ati ti igi ọ̀pẹ sí orí àwọn ìtẹ́lẹ̀ ati ìtẹ́dìí yìí, bí ààyè ti wà fún olukuluku sí; ó sì ṣe òdòdó sí i yípo.

37 Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe ṣe ìtẹ́lẹ̀ mẹ́wẹ̀ẹ̀wá, bákan náà ni ó da gbogbo wọn, bákan náà ni wọ́n tó, bákan náà ni wọn sì rí.

38 Ó ṣe abọ́ bàbà ńlá mẹ́wàá, ọ̀kọ̀ọ̀kan gba igba galọọnu, ó sì jẹ́ igbọnwọ mẹrin. Abọ́ kọ̀ọ̀kan sì wà lórí ìtẹ̀lẹ̀ mẹ́wẹ̀ẹ̀wá.

39 Ó to ìtẹ́lẹ̀ marun-un marun-un sí apá ìhà gúsù ati apá ìhà àríwá ilé náà, ó sì gbé agbada omi sí igun tí ó wà ní agbedemeji ìhà gúsù ati ìhà ìlà oòrùn ilé náà.

Ìṣírò Àwọn Ohun Èlò Tí Ó Wà ninu Ilé OLUWA

40 Huramu mọ ọpọlọpọ ìkòkò, ó fi irin rọ ọkọ́ pupọ, ó sì ṣe àwọn àwo kòtò. Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe parí iṣẹ́ tí ó bá Solomoni ọba ṣe ninu ilé OLUWA.

41 Àwọn iṣẹ́ náà nìwọ̀nyí: Òpó meji, ati àwọn ọpọ́n rìbìtì rìbìtì meji tí ó wà lórí àwọn òpó náà, ati iṣẹ́ ọnà tí ó ṣe sí ara àwo meji tí ó wà lórí ọpọ́n.

42 Àwọn irinwo pomegiranate tí wọ́n tò sí ìlà meji yí ọpọ́n bìrìkìtì bìrìkìtì orí àwọn òpó náà ká, ní ọgọọgọrun-un.

43 Ó ṣe agbada omi mẹ́wàá ati ìtẹ́dìí kọ̀ọ̀kan fún wọn.

44 Ó ṣe agbada omi ńlá kan ati àwọn ère mààlúù mejila tí wọ́n wà ní abẹ́ rẹ̀.

45 Bàbà dídán ni Huramu fi ṣe àwọn ìkòkò ati ọkọ́ ati àwokòtò ati gbogbo ohun èlò inú ilé OLUWA tí ó ṣe fún Solomoni ọba.

46 Ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jọdani tí ó jẹ́ ilẹ̀ amọ̀, láàrin Sukotu ati Saretani, ni ọba ti ṣe wọ́n.

47 Solomoni kò wọn àwọn ohun èlò tí ó ṣe, nítorí wọ́n pọ̀ yanturu. Nítorí náà kò mọ ìwọ̀n bàbà tí ó lò.

48 Solomoni ṣe gbogbo àwọn ohun èlò wọnyi sinu ilé OLUWA: pẹpẹ wúrà, tabili wúrà fún burẹdi ìfihàn;

49 àwọn ọ̀pá fìtílà tí wọ́n fi ojúlówó wúrà ṣe: marun-un ní ìhà àríwá, ati marun-un ní ìhà gúsù níwájú Ibi-Mímọ́-Jùlọ; àwọn òdòdó, àwọn fìtílà, ati àwọn ẹ̀mú wúrà,

50 àwọn ife ati ọ̀pá tí wọ́n fi ń pa iná ẹnu fìtílà; àwokòtò ati àwo turari, àwo ìfọnná tí wọ́n fi ojúlówó wúrà ṣe, wọ́n fi wúrà ṣe àwọn ihò àgbékọ́ ìlẹ̀kùn Ibi-Mímọ́-Jùlọ ati ti ìlẹ̀kùn gbọ̀ngàn Tẹmpili náà.

51 Bẹ́ẹ̀ ni Solomoni ọba ṣe parí gbogbo iṣẹ́ kíkọ́ ilé OLUWA, ó kó gbogbo fadaka, wúrà, ati àwọn ohun èlò inú ilé ìsìn, tí Dafidi, baba rẹ̀, ti yà sí mímọ́ wá, ó sì fi wọ́n pamọ́ sinu àwọn ilé ìṣúra tí ó wà ninu ilé OLUWA.

Categories
ÀWỌN ỌBA KINNI

ÀWỌN ỌBA KINNI 8

Wọ́n Gbé Àpótí Ẹ̀rí Wá sí inú Tẹmpili

1 Lẹ́yìn náà, Solomoni ọba ranṣẹ sí àwọn àgbààgbà Israẹli: àwọn olórí ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan, ati gbogbo àwọn olórí ìdílé kọ̀ọ̀kan, ó pè wọ́n jọ sí Jerusalẹmu láti gbé Àpótí Ẹ̀rí OLUWA láti Sioni, ìlú Dafidi, wá sinu ilé OLÚWA.

2 Gbogbo wọ́n bá péjọ siwaju rẹ̀ ní àkókò àjọ̀dún, ní oṣù Etanimu, tíí ṣe oṣù keje ọdún.

3 Lẹ́yìn tí gbogbo àwọn àgbààgbà ti péjọ, àwọn alufaa gbé Àpótí Ẹ̀rí náà.

4 Àwọn ọmọ Lefi ati àwọn alufaa gbé Àpótí OLUWA wá, ati Àgọ́ OLUWA, ati àwọn ohun èlò mímọ́ tí ó wà ninu rẹ̀.

5 Solomoni ọba ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli péjọ níwájú Àpótí Ẹ̀rí OLUWA, wọ́n sì fi ọpọlọpọ aguntan ati mààlúù tí ẹnikẹ́ni kò lè kà rúbọ.

6 Lẹ́yìn náà, àwọn alufaa gbé Àpótí Ẹ̀rí OLUWA wá sí ààyè rẹ̀ ninu ibi mímọ́ ti inú, ní Ibi-Mímọ́-Jùlọ, lábẹ́ ìyẹ́ àwọn kerubu.

7 Nítorí àwọn kerubu yìí na ìyẹ́ wọn bo ibi tí wọ́n gbé Àpótí Ẹ̀rí náà sí, wọ́n sì dàbí ìbòrí fún Àpótí Ẹ̀rí ati àwọn ọ̀pá rẹ̀.

8 Àwọn ọ̀pá tí wọ́n fi ń gbé Àpótí Ẹ̀rí náà gùn tóbẹ́ẹ̀ tí ẹni tí ó bá dúró ninu Ibi-Mímọ́ fi lè rí orí wọn níwájú Ibi-Mímọ́ ti inú. Ṣugbọn ẹnikẹ́ni kò lè rí wọn láti ìta. Àwọn ọ̀pá náà wà níbẹ̀ títí di òní yìí.

9 Kò sí ohunkohun ninu Àpótí Ẹ̀rí náà, àfi tabili òkúta meji tí Mose kó sinu rẹ̀ ní òkè Sinai, níbi tí OLUWA ti bá àwọn ọmọ Israẹli dá majẹmu, nígbà tí wọn ń ti Ijipti bọ̀.

10 Bí àwọn alufaa ti jáde láti inú Ibi-Mímọ́ náà, ìkùukùu kún inú rẹ̀,

11 tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn alufaa kò lè dúró láti ṣe iṣẹ́ ìsìn, nítorí ògo OLUWA kún inú ilé OLUWA.

12 Solomoni bá gbadura, ó ní,

“OLUWA, ìwọ ni o fi oòrùn sí ojú ọ̀run,

ṣugbọn sibẹsibẹ o yàn láti gbé inú ìkùukùu

ati òkùnkùn biribiri.

13 Nisinsinyii mo ti kọ́ ilé kan tí ó lọ́lá fún ọ,

níbi tí o óo máa gbé títí lae.”

Ọ̀rọ̀ Tí Solomoni Bá Àwọn Eniyan Sọ

14 Solomoni ọba yipada, ó kọjú sí àwọn eniyan níbi tí wọ́n dúró sí, ó sì súre fún wọn.

15 Ó ní, “Ìyìn ni fún OLUWA Ọlọrun Israẹli, tí ó mú ìlérí tí ó ṣe fún Dafidi, baba mi, ṣẹ, tí ó ní,

16 ‘Láti ìgbà tí mo ti kó àwọn eniyan mi jáde láti ilẹ̀ Ijipti, n kò yan ìlú kan ninu gbogbo ilẹ̀ Israẹli pé kí àwọn ọmọ Israẹli kọ́ ilé ìsìn sibẹ, níbi tí wọn óo ti máa sìn mí, ṣugbọn, mo yan Dafidi láti jọba lórí Israẹli, eniyan mi.’ ”

17 Solomoni tún fi kún un pé, “Ó jẹ́ èrò ọkàn baba mi láti kọ́ ilé fún OLUWA Ọlọrun Israẹli.

18 Ṣugbọn OLUWA sọ fún un pé nítòótọ́, ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ ni láti kọ́ ilé fún mi, ó sì dára bẹ́ẹ̀,

19 ṣugbọn kì í ṣe òun ni yóo kọ́ ilé ìsìn náà, ọmọ bíbí rẹ̀ ni yóo kọ́ ọ.

20 “Nisinsinyii OLUWA ti mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ: mo ti gorí oyè lẹ́yìn Dafidi, baba mi, mo ti jọba ní ilẹ̀ Israẹli bí OLUWA ti ṣèlérí; mo sì ti kọ́ ilé fún OLUWA Ọlọrun Israẹli.

21 Mo ti ṣètò ibìkan ninu ilé náà fún Àpótí Ẹ̀rí OLUWA, tí tabili òkúta tí wọ́n kọ majẹmu sí wà ninu rẹ̀, majẹmu tí OLUWA bá àwọn baba ńlá wa dá nígbà tí ó ń kó wọn jáde láti ilẹ̀ Ijipti.”

Adura Solomoni

22 Solomoni dúró níwájú pẹpẹ níwájú àwùjọ àwọn ọmọ Israẹli, ó gbé ọwọ́ rẹ̀ mejeeji sókè.

23 Ó bẹ̀rẹ̀ sí gbadura, ó ní, “OLUWA Ọlọrun Israẹli, kò sí Ọlọrun kan tí ó dàbí rẹ̀ lókè ọ̀run tabi ní ayé yìí, tíí máa pa majẹmu rẹ̀ mọ́, tíí sì máa fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ hàn sí àwọn iranṣẹ rẹ̀, tí ń fi tọkàntọkàn gbọ́ràn sí i lẹ́nu.

24 O ti mú ìlérí tí o ṣe fún iranṣẹ rẹ, Dafidi, baba mi, ṣẹ. O ṣe ìlérí fún un nítòótọ́, o sì mú un ṣẹ lónìí.

25 Ǹjẹ́ nisinsinyii, OLUWA Ọlọrun Israẹli, mo bẹ̀ ọ́, mú àwọn ìlérí tí o ṣe fún iranṣẹ rẹ, Dafidi, baba mi ṣẹ, pé, arọmọdọmọ rẹ̀ ni yóo máa jọba ní Israẹli títí lae, bí wọ́n bá ṣọ́ra ní ọ̀nà wọn, tí wọ́n sì bá mi rìn bí ìwọ ti bá mi rìn.

26 Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun Israẹli, mú ìlérí tí o ṣe fún iranṣẹ rẹ, Dafidi, baba mi ṣẹ.

27 “Ṣugbọn, ǹjẹ́ ìwọ Ọlọrun lè gbé inú ayé yìí? Nítorí pé bí gbogbo ọ̀run ti tóbi tó, kò gbà ọ́; kí á má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ ti ilé ìsìn tí mo kọ́ fún ọ?

28 OLUWA Ọlọrun mi, fi etí sí adura èmi iranṣẹ rẹ, kí o sì gbọ́ ẹ̀bẹ̀ tí mò ń bẹ̀ níwájú rẹ lónìí.

29 Kí ojú rẹ lè máa wà lára ilé ìsìn yìí tọ̀sán-tòru, níbi tí o sọ pé o óo yà sọ́tọ̀ fún orúkọ rẹ. Kí o lè gbọ́ adura tí iranṣẹ rẹ ń gbà sí ibí yìí.

30 Máa gbọ́ ẹ̀bẹ̀ iranṣẹ rẹ ati adura àwọn ọmọ Israẹli, eniyan rẹ, nígbà tí wọ́n bá kọjú sí ilé yìí, tí wọ́n sì gbadura, máa gbọ́ tiwa láti ibùgbé rẹ lọ́run, kí o sì máa dáríjì wá.

31 “Bí ẹnìkan bá ṣẹ ọmọnikeji rẹ̀ tí wọ́n sì ní kí ó wá búra, tí ó bá wá tí ó sì búra níwájú pẹpẹ rẹ ninu ilé ìsìn yìí,

32 OLUWA, gbọ́ lọ́run lọ́hùn-ún, kí o sì ṣe ìdájọ́ àwọn iranṣẹ rẹ. Jẹ ẹni tí ó bá jẹ̀bi ní ìyà gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀; dá ẹni tí ó bá jàre láre, kí o sì san ẹ̀san òdodo rẹ̀ fún un.

33 “Nígbà tí àwọn ọ̀tá bá ṣẹgun àwọn ọmọ Israẹli, eniyan rẹ, nítorí pé wọ́n dẹ́ṣẹ̀ sí ọ́, lẹ́yìn náà, tí wọ́n bá tún yipada sí ọ, tí wọ́n jẹ́wọ́ orúkọ rẹ ninu ilé yìí, tí wọ́n gbadura sí ọ, tí wọ́n bẹ̀bẹ̀,

34 gbọ́ adura wọn lọ́run lọ́hùn-ún, dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n, kí o sì mú wọn pada wá sórí ilẹ̀ tí o fún àwọn baba ńlá wọn.

35 “Nígbà tí o kò bá jẹ́ kí òjò rọ̀, nítorí pé wọ́n ṣẹ̀ ọ́, tí wọ́n bá ronupiwada tí wọ́n sì kọjú sí ilé ìsìn yìí, tí wọ́n gbadura sí ọ, nígbà tí o bá jẹ wọ́n níyà,

36 gbọ́ adura wọn lọ́run lọ́hùn-ún, dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji Israẹli, iranṣẹ rẹ, àní, àwọn eniyan rẹ, kí o sì kọ́ wọn ní ọ̀nà rere tí wọn yóo máa tọ̀; lẹ́yìn náà, rọ òjò sórí ilẹ̀ rẹ tí o fi fún àwọn eniyan rẹ bí ohun ìní.

37 “Nígbà tí ìyàn bá mú ní ilẹ̀ yìí, tabi tí àjàkálẹ̀ àrùn wà, tabi ìrẹ̀dànù èso, tabi tí ọ̀wọ́ eṣú, tabi tí àwọn kòkòrò bá jẹ ohun ọ̀gbìn oko run, tabi tí àwọn ọ̀tá bá dó ti èyíkéyìí ninu ìlú àwọn eniyan rẹ, tabi tí àìsàn, tabi àrùnkárùn kan bá wà láàrin wọn,

38 gbọ́ adura tí wọ́n bá gbà, ati ẹ̀bẹ̀ tí ẹnikẹ́ni tabi gbogbo Israẹli, àwọn eniyan rẹ, bá bẹ̀, nítorí ìpọ́njú ọkàn olukuluku wọn. Tí wọ́n bá gbé ọwọ́ wọn sókè, tí wọ́n sì kọjú sí ilé ìsìn yìí,

39 gbọ́ adura wọn láti ibùgbé rẹ lọ́run, dáríjì wọ́n, dá wọn lóhùn, kí o sì san ẹ̀san fún olukuluku gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀, (nítorí ìwọ nìkan ni o mọ èrò ọkàn ọmọ eniyan);

40 kí wọ́n lè máa bẹ̀rù rẹ ní gbogbo ọjọ́ tí wọ́n óo gbé lórí ilẹ̀ tí o fi fún àwọn baba ńlá wọn.

41 “Bákan náà, nígbà tí àlejò kan, tí kì í ṣe ọmọ Israẹli, bá wá láti ilẹ̀ òkèèrè nítorí orúkọ rẹ,

42 (nítorí wọn óo gbọ́ òkìkí rẹ, ati iṣẹ́ ìyanu tí o ti ṣe fún àwọn eniyan rẹ); tí ó bá wá sìn ọ́, tí ó bá kọjú sí ilé yìí, tí ó gbadura,

43 gbọ́ adura rẹ̀ láti ibùgbé rẹ lọ́run, kí o sì ṣe gbogbo ohun tí ó bá bèèrè fún un, kí gbogbo aráyé lè mọ orúkọ rẹ, kí wọ́n sì lè bẹ̀rù rẹ bí àwọn ọmọ Israẹli, àwọn eniyan rẹ tí ń ṣe, wọn yóo sì mọ̀ pé ilé ìsìn rẹ ni ilé tí mo kọ́ yìí.

44 “Nígbà tí àwọn eniyan rẹ bá lọ dojú kọ àwọn ọ̀tá wọn lójú ogun, níbikíbi tí o bá rán wọn lọ, tí wọ́n bá kọjú sí ìlú tí o yàn yìí, ati ilé ìsìn tí mo kọ́ fún ọ, tí wọ́n sì gbadura,

45 gbọ́ adura ati ẹ̀bẹ̀ wọn láti ọ̀run wá, kí o sì tì wọ́n lẹ́yìn.

46 “Nígbà tí àwọn eniyan rẹ bá ṣẹ̀ ọ́, (nítorí pé kò sí ẹni tí kì í dẹ́ṣẹ̀), tí o bá bínú sí wọn, tí o sì jẹ́ kí àwọn ọ̀tá ṣẹgun wọn, tí wọ́n sì kó wọn lẹ́rú lọ sí ilẹ̀ mìíràn, kì báà jẹ́ ibi tí ó jìnnà tabi tòsí,

47 bí wọ́n bá ronupiwada ní ilẹ̀ tí wọ́n kó wọn lẹ́rú lọ, tí wọ́n sì rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí ọ, tí wọ́n bá jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n dá, ati ìwà burúkú tí wọ́n hù,

48 tí wọ́n bá ronupiwada tọkàntọkàn ní ilẹ̀ àwọn ọ̀tá wọn tí ó kó wọn lẹ́rú, tí wọ́n bá kọjú sí ilẹ̀ tí o fi fún àwọn baba ńlá wọn, ati ìlú tí o yàn yìí, ati ilé ìsìn tí mo kọ́ ní orúkọ rẹ, tí wọ́n bá gbadura sí ọ;

49 gbọ́ adura ati ẹ̀bẹ̀ wọn láti ibùgbé rẹ lọ́run, kí o sì tì wọ́n lẹ́yìn.

50 Dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n, ati gbogbo àìdára tí wọ́n ṣe, kí o sì jẹ́ kí àwọn tí wọ́n kó wọn lẹ́rú ṣàánú wọn.

51 Eniyan rẹ sá ni wọ́n, ìwọ ni o sì ni wọ́n, ìwọ ni o kó wọn jáde láti ilẹ̀ Ijipti, ilẹ̀ tí ó gbóná janjan bí iná ìléru.

52 “OLUWA Ọlọrun, fi ojurere wo àwa iranṣẹ rẹ, àní àwọn ọmọ Israẹli, eniyan rẹ, kí o sì gbọ́ adura ati ẹ̀bẹ̀ wọn nígbàkúùgbà tí wọ́n bá ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́.

53 OLUWA Ọlọrun, ìwọ ni o yà wọ́n sọ́tọ̀ láàrin gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ayé, pé kí wọ́n jẹ́ ìní rẹ, gẹ́gẹ́ bí o ti sọ fún wọn láti ẹnu Mose, iranṣẹ rẹ, nígbà tí ó kó àwọn baba ńlá wa jáde ní ilẹ̀ Ijipti.”

Adura Ìparí

54 Nígbà ti Solomoni parí adura ati ẹ̀bẹ̀ rẹ̀ sí OLUWA, ó dìde kúrò níwájú pẹpẹ níbi tí ó kúnlẹ̀ sí, tí ó sì gbé ọwọ́ sókè.

55 Ó dìde dúró, ó sì súre fún gbogbo ìjọ ọmọ Israẹli, ó gbadura sókè pé,

56 “Ìyìn ni fún OLUWA, tí ó fún àwọn eniyan rẹ̀ ní ìsinmi gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ̀. Ó ti mú gbogbo ìlérí rere rẹ̀ tí ó ṣe láti ẹnu Mose, iranṣẹ rẹ̀, ṣẹ.

57 Kí OLUWA Ọlọrun wa kí ó wà pẹlu wa, bí ó ti wà pẹlu àwọn baba ńlá wa; kí ó má fi wá sílẹ̀, kí ó má sì kọ̀ wá sílẹ̀,

58 kí ó ṣe wá ní ẹni tí yóo gbọ́ràn sí òun lẹ́nu, kí á lè máa tọ ọ̀nà rẹ̀, kí á lè máa pa àwọn òfin ati ìlànà rẹ̀ tí ó fi fún àwọn baba ńlá wa mọ́.

59 Kí OLUWA Ọlọrun wa ranti adura mi yìí ati gbogbo ẹ̀bẹ̀ tí mo bẹ̀ níwájú rẹ̀ yìí tọ̀sán-tòru, kí ó máa ti èmi iranṣẹ rẹ̀ lẹ́yìn nígbà gbogbo, ati àwọn ọmọ Israẹli, eniyan rẹ̀ pẹlu; máa tì wá lẹ́yìn bí ó bá ti tọ́ lojoojumọ,

60 kí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ayé lè mọ̀ pé OLUWA ni Ọlọrun, ati pé kò sí ẹlòmíràn mọ́.

61 Ẹ fi tọkàntọkàn jẹ́ olóòótọ́ sí OLUWA Ọlọrun wa, kí ẹ tẹ̀lé ìlànà rẹ̀, kí ẹ sì máa pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́ bí ẹ ti ń ṣe lónìí.”

Yíya Ilé OLUWA sí Mímọ́

62 Lẹ́yìn náà, Solomoni ọba ati gbogbo àwọn eniyan rú ẹbọ sí OLUWA.

63 Solomoni fi ọ̀kẹ́ kan ati ẹgbaa (22,000) mààlúù, ati ọ̀kẹ́ mẹfa (120,000) aguntan rú ẹbọ alaafia sí OLUWA. Bẹ́ẹ̀ ni òun ati àwọn ọmọ Israẹli ṣe ya ilé OLUWA náà sí mímọ́.

64 Ní ọjọ́ kan náà, ọba ya ààrin gbùngbùn àgbàlá tí ó wà níwájú ilé ìsìn sí mímọ́. Níbẹ̀ ni ó ti rú ẹbọ sísun, ati ẹbọ ohun jíjẹ, ati ti ọ̀rá ẹran tí ó fi rú ẹbọ alaafia; nítorí pé pẹpẹ bàbà tí ó wà níwájú OLUWA kéré jù fún àpapọ̀ gbogbo àwọn ẹbọ wọnyi.

65 Solomoni ati àwọn ọmọ Israẹli ṣe Àjọ̀dún Àgọ́ Àjọ níbẹ̀. Ogunlọ́gọ̀ àwọn eniyan láti Ẹnu Ọ̀nà Hamati títí dé odò kékeré Ijipti ni wọ́n péjọ níwájú OLUWA fún ọjọ́ meje.

66 Ní ọjọ́ kẹjọ Solomoni tú àwọn eniyan náà ká lọ sí ilé wọn. Gbogbo wọn ni wọ́n súre fún ọba, wọ́n sì pada sílé pẹlu inú dídùn; nítorí gbogbo oore tí OLUWA ti ṣe fún Dafidi, iranṣẹ rẹ̀, ati fún àwọn ọmọ Israẹli, eniyan rẹ̀.

Categories
ÀWỌN ỌBA KINNI

ÀWỌN ỌBA KINNI 9

Ọlọrun Tún Fara han Solomoni

1 Lẹ́yìn tí Solomoni ọba ti kọ́ ilé OLUWA ati ààfin rẹ̀ tán, ati gbogbo ilé tí ó fẹ́ kọ́.

2 OLUWA tún fi ara hàn án lẹẹkeji, bí ó ti fara hàn án ní Gibeoni,

3 ó wí fún un pé, “Mo ti gbọ́ adura ati ẹ̀bẹ̀ rẹ, mo sì ti ya ilé tí o kọ́ yìí sí mímọ́. Ibẹ̀ ni wọn óo ti máa sìn mí títí lae. N óo máa mójú tó o, n óo sì máa dáàbò bò ó nígbà gbogbo.

4 Bí o bá sìn mí tọkàntọkàn pẹlu òtítọ́ inú, gẹ́gẹ́ bí Dafidi, baba rẹ, ti ṣe, bí o bá ṣe gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún ọ, tí o sì pa òfin ati ìlànà mi mọ́,

5 n óo fìdí ìjọba rẹ múlẹ̀ ní Israẹli, gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣèlérí fún Dafidi, baba rẹ, pé arọmọdọmọ rẹ̀ ni yóo máa jọba lórí àwọn ọmọ Israẹli títí lae.

6 Ṣugbọn bí ìwọ tabi arọmọdọmọ rẹ bá yapa kúrò lẹ́yìn mi, tí ẹ bá ṣe àìgbọràn sí àwọn òfin ati ìlànà tí mo fi lélẹ̀ fún yín, tí ẹ bẹ̀rẹ̀ sí bọ oriṣa,

7 n óo mú àwọn ọmọ Israẹli kúrò lórí ilẹ̀ tí mo fún wọn, n óo sì kọ ilé ìsìn tí mo ti yà sí mímọ́ fún orúkọ mi sílẹ̀. Gbogbo ọmọ Israẹli yóo di ẹni àmúpòwe ati ẹlẹ́yà láàrin àwọn orílẹ̀-èdè yòókù.

8 Ilé yìí yóo di òkìtì àlàpà, yóo sì di ohun àwòyanu ati ẹ̀gàn fún gbogbo ẹni tí ó bá ń rékọjá lọ. Wọn óo máa bi ara wọn léèrè pé, ‘Kí ló dé tí OLUWA fi ṣe báyìí sí ilẹ̀ yìí ati ilé yìí?’

9 Wọn óo sì dáhùn pé, ‘Ìdí tí OLUWA fi ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé, àwọn eniyan náà kọ OLUWA Ọlọrun wọn, tí ó kó àwọn baba ńlá wọn jáde láti ilẹ̀ Ijipti sílẹ̀, wọ́n sì lọ ń forí balẹ̀ fún àwọn oriṣa, wọ́n ń sìn wọ́n; nítorí náà ni OLUWA fi jẹ́ kí ibi ó bá wọn.’ ”

Solomoni ṣe Àdéhùn pẹlu Hiramu Ọba

10 Lẹ́yìn ogún ọdún tí Solomoni fi kọ́ ilé OLUWA ati ààfin rẹ̀,

11 tí Hiramu, ọba Tire sì ti fún un ní ìwọ̀n igi kedari, igi sipirẹsi ati wúrà tí ó fẹ́, fún iṣẹ́ náà, Solomoni fún Hiramu ní ogún ìlú ní agbègbè Galili.

12 Ṣugbọn nígbà tí Hiramu ọba wá láti Tire tí ó rí àwọn ìlú tí Solomoni fún un, wọn kò tẹ́ ẹ lọ́rùn rárá.

13 Ó bi Solomoni pé, “Arakunrin mi, irú àwọn ìlú wo ni o fún mi yìí?” Ìdí nìyí tí wọ́n fi ń pe ilẹ̀ náà ní Kabulu títí di òní olónìí.

14 Ọgọfa (120) ìwọ̀n talẹnti wúrà ni Hiramu ti fi ranṣẹ sí Solomoni ọba.

Àwọn Nǹkan Pataki Mìíràn Tí Solomoni Ṣe

15 Pẹlu ipá ni Solomoni ọba fi kó àwọn eniyan ṣiṣẹ́, tí ó fi kọ́ ilé OLUWA ati ààfin rẹ̀, ó sì kọ́ Milo, ati odi Jerusalẹmu, ati ìlú Hasori, ìlú Megido ati ìlú Geseri.

16 (Farao, ọba Ijipti ti gbógun ti ìlú Geseri ó sì dáná sun ún, ó pa gbogbo àwọn ará Kenaani tí wọn ń gbé inú rẹ̀. Ó fi ìlú náà ṣe ẹ̀bùn igbeyawo fún ọmọ rẹ̀ obinrin, nígbà tí ó fẹ́ Solomoni ọba.

17 Nítorí náà ni Solomoni ṣe tún ìlú náà kọ́.) Pẹlu apá ìsàlẹ̀ Beti Horoni,

18 ati ìlú Baalati, ati Tamari tí ó wà ní aṣálẹ̀ Juda,

19 ati àwọn ìlú tí ó ń kó àwọn ohun èlò rẹ̀ pamọ́ sí, ati àwọn ìlú tí ó ń kó kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ sí, ati àwọn ìlú tí àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀ ń gbé, ati gbogbo ilé yòókù tí ó wu Solomoni láti kọ́ ní Jerusalẹmu, ní Lẹbanoni, ati ní àwọn ibòmíràn ninu ìjọba rẹ̀.

20 Gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n ṣẹ́kù lára àwọn ará Amori, ati àwọn ará Hiti, ati àwọn ará Perisi, ati àwọn ará Hifi ati àwọn ará Jebusi, àwọn tí kì í ṣe ara àwọn ọmọ Israẹli–

21 arọmọdọmọ wọn tí wọ́n ṣẹ́kù, tí àwọn ọmọ Israẹli kò lè parun, ni Solomoni kó lẹ́rú pẹlu ipá, wọ́n sì wà bẹ́ẹ̀ títí di òní yìí.

22 Ṣugbọn Solomoni kò fi àwọn ọmọ Israẹli ṣe ẹrú. Àwọn ni ó ń lò gẹ́gẹ́ bí ọmọ ogun, ati olórí àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀; àwọn ni balogun rẹ̀, ati àwọn ọ̀gágun rẹ̀; àwọn ni ọ̀gá àwọn tí ń darí kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ ati àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀.

23 Ẹgbẹta ó dín aadọta (550) ni àwọn lọ́gàálọ́gàá tí Solomoni fi ṣe alákòóso àwọn tí ó ń kó ṣiṣẹ́ tipátipá, níbi oríṣìíríṣìí iṣẹ́ ilé kíkọ́ rẹ̀.

24 Nígbà tí ó yá, ọmọ ọba Farao, iyawo Solomoni kó kúrò ní ìlú Dafidi, ó lọ sí ilé tí Solomoni kọ́ fún un. Lẹ́yìn náà ni Solomoni kọ́ ìlú Milo.

25 Ẹẹmẹta lọ́dún ni Solomoni máa ń rú ẹbọ sísun ati ẹbọ alaafia lórí pẹpẹ tí ó kọ́ fún OLUWA, a sì máa sun turari níwájú OLUWA. Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe parí kíkọ́ ilé náà.

26 Solomoni kan ọpọlọpọ ọkọ̀ ojú omi ní Esiongeberi lẹ́bàá Eloti, ní etí Òkun Pupa ní ilẹ̀ Edomu.

27 Hiramu ọba fi àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ tí wọ́n mọ̀ nípa ọkọ̀ ojú omi, lé àwọn ọkọ̀ náà, ó kó wọn rán àwọn iranṣẹ Solomoni sí i.

28 Wọ́n tu ọkọ̀ lọ sí ilẹ̀ Ofiri, wọ́n sì kó wúrà tí ó tó okoolenirinwo (420) ìwọ̀n talẹnti bọ̀ wá fún Solomoni ọba.