Categories
ÀWỌN ỌBA KEJI

ÀWỌN ỌBA KEJI 20

Àìsàn Hesekaya Ọba, ati Ìwòsàn Rẹ̀

1 Ní àkókò kan Hesekaya ṣàìsàn tóbẹ́ẹ̀ tí ó fẹ́rẹ̀ kú. Wolii Aisaya ọmọ Amosi, wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sọ fún un pé, “OLUWA ní kí o palẹ̀ ilé rẹ mọ́ nítorí pé kíkú ni o óo kú, o kò ní yè.”

2 Hesekaya bá kọjú sí ògiri, ó sì gbadura sí OLUWA, ó ní,

3 “Mo bẹ̀ ọ́ OLUWA, ranti bí mo ti sìn ọ́ pẹlu òtítọ́ ati ọkàn pípé, ati bí mo ti ń ṣe ohun tí o fẹ́.” Ó sì sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn.

4 Aisaya jáde kúrò lọ́dọ̀ ọba, ṣugbọn kí ó tó jáde kúrò ní àgbàlá ààfin, OLUWA sọ fún un pé,

5 “Pada lọ sọ́dọ̀ Hesekaya, olórí àwọn eniyan mi, kí o sì sọ fún un pé, ‘Èmi OLUWA Ọlọrun Dafidi baba ńlá rẹ̀ ti gbọ́ adura rẹ̀, mo sì ti rí omijé rẹ̀. N óo wò ó sàn, ní ọjọ́ kẹta, yóo lọ sí ilé OLUWA,

6 n óo sì jẹ́ kí ó gbé ọdún mẹẹdogun sí i. N óo gba òun ati Jerusalẹmu lọ́wọ́ ọba Asiria. N óo sì dáàbò bo ìlú yìí nítorí tèmi fúnra mi ati nítorí ìlérí tí mo ṣe fún Dafidi, iranṣẹ mi.’ ”

7 Aisaya bá sọ fún àwọn iranṣẹ ọba pé kí wọ́n fi èso ọ̀pọ̀tọ́ sí orí oówo rẹ̀, kí ara rẹ̀ lè dá.

8 Hesekaya ọba bèèrè pé, “Kí ni yóo jẹ́ àmì pé OLUWA yóo wò mí sàn, ati pé n óo lọ sí ilé OLUWA ní ọjọ́ kẹta?”

9 Aisaya dáhùn pé, “OLUWA yóo fún ọ ní àmì láti fihàn pé òun yóo mú ìlérí òun ṣẹ. Èwo ni o fẹ́, ninu kí òjìji lọ siwaju ní ẹsẹ̀ mẹ́wàá tabi kí ó pada sẹ́yìn ní ẹsẹ̀ mẹ́wàá?”

10 Hesekaya dáhùn pé, “Ó rọrùn fún òjìji láti lọ siwaju ní ẹsẹ̀ mẹ́wàá, kí ó pada sẹ́yìn ni mo fẹ́.”

11 Aisaya gbadura sí OLUWA, OLUWA sì mú kí òjìji pada sẹ́yìn ní ẹsẹ̀ mẹ́wàá lára àtẹ̀gùn ilé tí ọba Ahasi ṣe.

Àwọn Iranṣẹ láti Babiloni

12 Ní àkókò kan náà ni Merodaki Baladani, ọmọ Baladani, ọba Babiloni, fi ìwé ati ẹ̀bùn ranṣẹ sí Hesekaya nítorí ó gbọ́ pé Hesekaya ń ṣe àìsàn.

13 Hesekaya gba àwọn oníṣẹ́ náà ní àlejò. Ó fi gbogbo ilé ìṣúra rẹ̀, fadaka, wúrà, turari, òróró iyebíye ati gbogbo ohun ìjà rẹ̀ hàn wọ́n. Kò sí ohun kan ninu ilé ìṣúra rẹ̀ ati ní gbogbo ìjọba rẹ̀ tí kò fihàn wọ́n.

14 Nígbà náà ni wolii Aisaya lọ sí ọ̀dọ̀ Hesekaya, ó bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Níbo ni àwọn ọkunrin wọnyi ti wá, kí ni wọ́n sì sọ fún ọ?”

Hesekaya dáhùn pé, “Ọ̀nà jíjìn ni wọ́n ti wá, láti Babiloni.”

15 Aisaya bá tún bèèrè pé, “Kí ni wọ́n rí ninu ààfin rẹ?”

Ọba dáhùn, ó ní, “Kò sí ohun kan ninu ilé ìṣúra tí n kò fi hàn wọ́n.”

16 Nígbà náà ni Aisaya sọ fún ọba pé, “OLUWA ní,

17 ‘Àkókò kan ń bọ̀ tí wọn yóo kó gbogbo ohun tí ó wà ninu ààfin rẹ lọ sí Babiloni, gbogbo ohun tí àwọn baba ńlá rẹ ti kó jọ látẹ̀yìnwá títí di òní ni wọn óo kó lọ, wọn kò ní fi nǹkankan sílẹ̀.

18 Wọn yóo kó ninu àwọn ọmọ rẹ lọ fi ṣe ìwẹ̀fà ní ààfin ọba Babiloni.’ ”

19 Hesekaya sọ fún Aisaya pé, “Ọ̀rọ̀ OLUWA tí o sọ dára.” Nítorí ó wí ninu ara rẹ̀ pé, alaafia ati ìfọ̀kànbalẹ̀ yóo sá wà ní àkókò tòun.

Ìgbẹ̀yìn Ìjọba Hesekaya

20 Gbogbo nǹkan yòókù tí Hesekaya ṣe, ìwà akọni rẹ̀ ati bí ó ti ṣe adágún omi ati ọ̀nà omi wọ inú ìlú ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Juda.

21 Hesekaya kú, wọ́n sì sin ín sinu ibojì àwọn baba rẹ̀; Manase ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀.

Categories
ÀWỌN ỌBA KEJI

ÀWỌN ỌBA KEJI 21

Manase, Ọba Juda

1 Ọmọ ọdún mejila ni Manase nígbà tí ó jọba, ó sì wà lórí oyè ní Jerusalẹmu fún ọdún marundinlọgọta. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Hefisiba.

2 Manase ṣe nǹkan tí ó burú lójú OLUWA nítorí pé ó tẹ̀lé ìwà ìríra àwọn eniyan ilẹ̀ náà, tí OLUWA lé jáde kúrò níwájú àwọn ọmọ Israẹli.

3 Ó tún àwọn ilé oriṣa tí Hesekaya, baba rẹ̀ ti parun kọ́, ó kọ́ pẹpẹ ìrúbọ fún oriṣa Baali, ó sì gbẹ́ ère oriṣa Aṣera, bí Ahabu, ọba Israẹli, ti gbẹ́ ẹ. Ó sì ń bọ àwọn ìràwọ̀.

4 Ó kọ́ pẹpẹ ìrúbọ oriṣa sinu ilé OLUWA, níbi tí OLUWA ti pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli láti máa sin òun.

5 Ó kọ́ pẹpẹ ìrúbọ fún àwọn ìràwọ̀ ninu àwọn àgbàlá mejeeji tí wọ́n wà ninu ilé OLUWA.

6 Ó fi ọmọ rẹ̀ rú ẹbọ sísun, a máa ṣe àyẹ̀wò lọ́dọ̀ àwọn aláfọ̀ṣẹ, a sì máa ṣe àlúpàyídà. Bẹ́ẹ̀ ni ó máa ń wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ àwọn alásọtẹ́lẹ̀ ati àwọn abókùúsọ̀rọ̀. Ó hùwà tí ó burú gidigidi níwájú OLUWA, ó sì rú ibinu OLUWA sókè.

7 Ó gbẹ́ ère Aṣera tí ó gbé sinu ilé OLUWA, ibi tí OLUWA ti sọ fún Dafidi ati Solomoni pé, “Ninu ilé yìí, àní, ní Jerusalẹmu, ni mo yàn láàrin àwọn ìlú àwọn ẹ̀yà mejeejila Israẹli, gẹ́gẹ́ bí ibi tí ẹ óo ti máa sìn mí títí lae.

8 Ati pé bí àwọn ọmọ Israẹli bá júbà àṣẹ mi, tí wọ́n pa òfin mi, tí Mose, iranṣẹ mi, fún wọn mọ́, n kò ní jẹ́ kí á lé wọn kúrò lórí ilẹ̀ tí mo fún àwọn baba ńlá wọn.”

9 Ṣugbọn àwọn ọmọ ilẹ̀ Juda kò júbà OLUWA, Manase sì mú kí wọ́n dẹ́ṣẹ̀ tí ó burú ju èyí tí àwọn eniyan ilẹ̀ náà tẹ́lẹ̀ dá lọ, àní, àwọn tí OLUWA lé jáde kúrò níwájú àwọn ọmọ Israẹli.

10 OLUWA sọ láti ẹnu àwọn wolii, iranṣẹ rẹ̀, pé,

11 “Manase ọba ti ṣe àwọn ohun ìríra wọnyi, wọ́n burú ju èyí tí àwọn ará Kenaani ṣe lọ. Ó sì mú kí Juda dẹ́ṣẹ̀ nípa pé wọ́n ń bọ àwọn ère rẹ̀.

12 Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun Israẹli ní òun óo mú ìparun wá sórí Jerusalẹmu ati Juda, tóbẹ́ẹ̀ tí yóo jẹ́ ìyàlẹ́nu gidigidi fún ẹnikẹ́ni tí ó bá gbọ́.

13 Ó ní òun óo jẹ Jerusalẹmu níyà bí òun ti jẹ Samaria níyà. Ó ní bí òun ti ṣe sí ìdílé Ahabu ati àwọn ọmọ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni òun óo gbá àwọn eniyan náà kúrò ní Jerusalẹmu, bí àwo tí a nù tí a sì da ojú rẹ̀ bolẹ̀.

14 OLUWA ní òun óo kọ àwọn eniyan òun yòókù sílẹ̀, òun óo fi wọ́n lé àwọn ọ̀tá wọn lọ́wọ́, ọ̀tá yóo ṣẹgun wọn, wọn yóo sì kó wọn lọ bí ìkógun.

15 Nítorí pé wọ́n ti ṣe ohun burúkú lójú òun, wọ́n sì ti mú òun bínú láti ìgbà tí àwọn baba ńlá wọn ti kúrò ní Ijipti, àní títí di òní olónìí.”

16 Manase pa ọpọlọpọ àwọn eniyan aláìṣẹ̀ títí tí ẹ̀jẹ̀ fi ń ṣàn ní ìgboro Jerusalẹmu. Ó tún fa àwọn eniyan Juda sinu ẹ̀ṣẹ̀ ìbọ̀rìṣà; nípa bẹ́ẹ̀ ó mú kí wọ́n ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA.

17 Gbogbo nǹkan yòókù tí Manase ṣe ati àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí ó dá ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Juda.

18 Manase kú, wọ́n sì sin ín sinu ọgba Usa tí ó wà ní ààfin. Amoni ọmọ rẹ̀, sì jọba lẹ́yìn rẹ̀.

Amoni Ọba Juda

19 Ẹni ọdún mejilelogun ni Amoni nígbà tí ó jọba, ó sì wà lórí oyè ní Jerusalẹmu fún ọdún meji. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Meṣulemeti ọmọ Harusi ará Jotiba.

20 Ó ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA bí Manase, baba rẹ̀ ti ṣe.

21 Ó tẹ̀ sí ìwà ẹ̀ṣẹ̀ baba rẹ̀, ó sì bọ àwọn ère tí baba rẹ̀ bọ.

22 Ó kọ OLUWA Ọlọrun àwọn baba ńlá rẹ̀ sílẹ̀, kò sì júbà àṣẹ rẹ̀.

23 Àwọn iranṣẹ rẹ̀ dìtẹ̀ mọ́ ọn, wọ́n sì pa á ní ààfin rẹ̀.

24 Àwọn eniyan Juda pa àwọn tí wọ́n dìtẹ̀ mọ́ Amoni ọba, wọ́n sì fi Josaya ọmọ rẹ̀ jọba lẹ́yìn rẹ̀.

25 Gbogbo nǹkan yòókù tí Amoni ṣe ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Juda.

26 Wọ́n sin òkú rẹ̀ sinu ibojì tí ó wà ninu ọgbà Usa ní ààfin. Josaya, ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀.

Categories
ÀWỌN ỌBA KEJI

ÀWỌN ỌBA KEJI 22

Josaya, Ọba Juda

1 Ọmọ ọdún mẹjọ ni Josaya nígbà tí ó jọba, ó sì wà lórí oyè ní Jerusalẹmu fún ọdún mọkanlelọgbọn. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Jedida ọmọ Adaya ará Bosikati.

2 Ó ṣe ohun tí ó dára lójú OLUWA, ó tẹ̀ sí ọ̀nà Dafidi, baba ńlá rẹ̀, kò sì ṣe nǹkankan tí ó lòdì sí àpẹẹrẹ tí Dafidi fi lélẹ̀.

Wọ́n rí Ìwé Òfin

3 Ní ọdún kejidinlogun tí Josaya jọba, ó rán Ṣafani, akọ̀wé rẹ̀, ọmọ Asalaya, ọmọ Meṣulamu, sí ilé OLUWA pé kí ó

4 lọ sí ọ̀dọ̀ Hilikaya olórí alufaa, kí ó ṣírò iye owó tí àwọn alufaa tí wọ́n wà lẹ́nu ọ̀nà ti gbà lọ́wọ́ àwọn eniyan,

5 kí ó gbé owó náà fún àwọn tí wọ́n ń ṣe àkóso àtúnṣe ilé OLUWA. Àwọn ni wọn yóo máa san owó fún

6 àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà, àwọn ọ̀mọ̀lé ati àwọn agbẹ́kùúta, kí wọ́n sì ra igi ati òkúta tí wọn yóo lò fún àtúnṣe ilé OLUWA.

7 Ó ní àwọn tí wọ́n ń ṣe àkóso àtúnṣe ilé náà kò ní nílò láti ṣe ìṣirò owó tí wọn ń ná, nítorí pé gbogbo wọn ni wọ́n jẹ́ olóòótọ́.

8 Ṣafani jíṣẹ́ ọba fún Hilikaya; Hilikaya olórí alufaa, sì sọ fún un pé òun ti rí ìwé òfin ninu ilé OLUWA. Ó fún Ṣafani ní ìwé náà, ó sì kà á.

9 Ṣafani bá pada lọ jíṣẹ́ fún ọba, ó sọ fún ọba pé, àwọn iranṣẹ rẹ̀ ti kó owó tí ó wà ninu ilé OLUWA fún àwọn tí wọ́n ń ṣe àkóso àtúnṣe ilé OLUWA,

10 ati pé Hilikaya fún òun ní ìwé kan; ó sì kà á sí etígbọ̀ọ́ ọba.

11 Nígbà tí ọba gbọ́ ọ̀rọ̀ inú ìwé náà, ó fa aṣọ rẹ̀ ya láti fi ìbànújẹ́ rẹ̀ hàn.

12 Ó bá pàṣẹ fún Hilikaya alufaa, Ahikamu ọmọ Ṣafani, Akibori ọmọ Mikaya, Ṣafani, akọ̀wé, ati Asaya, iranṣẹ ọba pé,

13 “Ẹ lọ bèèrè ohun tí a kọ sinu ìwé yìí lọ́wọ́ OLUWA fún èmi ati fún gbogbo eniyan Juda. OLUWA ń bínú sí wa gidigidi nítorí pé àwọn baba ńlá wa kò ṣe ohun tí ìwé yìí pa láṣẹ fún wa.”

14 Hilikaya alufaa, ati Ahikamu ati Akibori ati Ṣafani ati Asaya bá lọ wádìí lọ́wọ́ wolii obinrin kan tí ń jẹ́ Hulida, tí ń gbé apá keji Jerusalẹmu. Ọkọ rẹ̀ ni Ṣalumu ọmọ Tikifa, ọmọ Harihasi tíí máa ń ṣe ìtọ́jú yàrá tí wọn ń kó aṣọ pamọ́ sí. Wọ́n sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún obinrin náà.

15 Ó bá rán wọn pada, ó ní: “Ẹ lọ sọ fún ẹni tí ó ran yín sí mi pé,

16 ‘OLUWA ní, “Wò ó n óo jẹ Jerusalẹmu ati àwọn eniyan inú rẹ̀ níyà bí a ti kọ ọ́ sinu ìwé tí ọba Juda kà.

17 Nítorí pé wọ́n ti kọ̀ mí sílẹ̀, wọ́n ń sun turari sí àwọn oriṣa láti mú mi bínú nítorí iṣẹ́ ọwọ́ wọn. Nítorí náà, inú mi yóo ru sí ibí yìí, kò sì ní rọlẹ̀.

18 Ṣugbọn níti ọba Juda tí ó sọ pé kí ẹ lọ wádìí lọ́wọ́ OLUWA, ẹ sọ fún un pé, OLUWA Ọlọrun Israẹli ní: Nípa ọ̀rọ̀ tí ó ti gbọ́, nítorí pé ó ronupiwada,

19 ó sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ níwájú OLUWA, ó fa aṣọ rẹ̀ ya ó sì sun ẹkún nígbà tí ó gbọ́ ìlérí ìjìyà tí mo ṣe nípa Jerusalẹmu ati àwọn eniyan ibẹ̀, pé n óo sọ Jerusalẹmu di ahoro ati ibi tí àwọn eniyan yóo máa lo orúkọ rẹ̀ láti gégùn-ún. Ṣugbọn mo ti gbọ́ adura rẹ̀ nítorí pé ó fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì sọkún níwájú mi.

20 Nítorí náà, n kò ní fi ìyà jẹ Jerusalẹmu nígbà tí ó wà láàyè, n óo jẹ́ kí ó kú ní alaafia.” ’ ”

Àwọn ọkunrin náà sì lọ jíṣẹ́ fún Josaya ọba.

Categories
ÀWỌN ỌBA KEJI

ÀWỌN ỌBA KEJI 23

Josaya pa Ìbọ̀rìṣà Run

1 Josaya bá pe ìpàdé gbogbo àwọn olórí Juda ati Jerusalẹmu.

2 Gbogbo wọn lọ sí ilé OLUWA pẹlu àwọn alufaa ati àwọn wolii ati gbogbo àwọn eniyan, àtọmọdé àtàgbà wọn. Ọba bá ka ìwé majẹmu tí wọ́n rí ninu ilé OLUWA sí etígbọ̀ọ́ wọn.

3 Ọba dúró sí ààyè rẹ̀, lẹ́bàá òpó, ó bá OLUWA dá majẹmu pé òun óo máa rìn ní ọ̀nà OLUWA ati láti pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́ ati láti mú gbogbo ohun tí ó wà ninu Ìwé náà ṣẹ. Gbogbo àwọn eniyan sì ṣe ìlérí láti pa majẹmu náà mọ́.

4 Josaya bá pàṣẹ fún Hilikaya olórí alufaa, ati àwọn alufaa yòókù ati àwọn tí wọn ń ṣọ́ ẹnu ọ̀nà ilé OLUWA, pé kí wọ́n kó gbogbo ohun èlò ìsìn oriṣa Baali, ati ti oriṣa Aṣera, ati ti àwọn ìràwọ̀ jáde. Ọba jó àwọn ohun èlò náà níná lẹ́yìn odi ìlú, lẹ́bàá àfonífojì Kidironi, ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n kó eérú wọn lọ sí Bẹtẹli.

5 Gbogbo àwọn alufaa tí àwọn ọba Juda ti yàn láti máa rúbọ lórí pẹpẹ oriṣa ní àwọn ìlú Juda ati ní agbègbè Jerusalẹmu ni Josaya dá dúró, ati gbogbo àwọn tí wọn ń rúbọ sí oriṣa Baali, sí oòrùn, òṣùpá, àwọn ìràwọ̀, ati àwọn nǹkan tí wọ́n wà ní òfuurufú.

6 Ó kó gbogbo àwọn ère oriṣa Aṣera tí ó wà ninu ilé OLUWA lọ sí àfonífojì Kidironi lẹ́yìn Jerusalẹmu. Ó sun wọ́n níná níbẹ̀, ó lọ̀ wọ́n lúbúlúbú, ó sì fọ́n eérú wọn ká sórí ibojì àwọn eniyan.

7 Ó wó gbogbo ibi tí àwọn tí wọ́n máa ń ṣe panṣaga fún ìsìn Aṣera ń gbé létí ilé OLUWA lulẹ̀, níbi tí àwọn obinrin ti máa ń hun aṣọ fún ìsìn Aṣera.

8 Gbogbo àwọn alufaa tí wọ́n wà káàkiri ilẹ̀ Juda ni ó mú wá sí Jerusalẹmu, ó sì ba gbogbo àwọn pẹpẹ ìrúbọ tí wọ́n ti ń rúbọ jẹ́. Ó wó pẹpẹ ìrúbọ tí ó wà ní ẹnubodè, tí Joṣua, baálẹ̀ ìlú kọ́, tí ó wà ní apá òsì, bí eniyan bá ti fẹ́ wọ ìlú.

9 Kò gba àwọn alufaa náà láàyè láti ṣiṣẹ́ ninu ilé OLUWA, ṣugbọn wọ́n lè jẹ ninu àkàrà tí wọn kò fi ìwúkàrà ṣe, tí ó jẹ́ ti àwọn alufaa ẹlẹgbẹ́ wọn.

10 Josaya Ọba wó ilé oriṣa Tofeti tí ó wà ní àfonífojì Hinomu, kí ẹnikẹ́ni má baà lè fi ọmọkunrin tabi ọmọbinrin rẹ̀ rúbọ sí oriṣa Moleki mọ́.

11 Ó tú gbogbo ẹṣin tí àwọn ọba Juda ti yà sọ́tọ̀ fún ìsìn oòrùn, ní ẹnu ọ̀nà ilé OLUWA, lẹ́bàá yàrá Natani Meleki, ìwẹ̀fà tí ó wà ní agbègbè ilé OLUWA; ó sì dáná sun àwọn kẹ̀kẹ́ ogun tí wọ́n yà sọ́tọ̀ fún ìsìn oòrùn.

12 Ó wó àwọn pẹpẹ ìrúbọ tí àwọn ọba Juda kọ́ sórí ilé Ahasi ninu ààfin lulẹ̀, pẹlu àwọn pẹpẹ ìrúbọ tí Manase kọ́ sinu àwọn àgbàlá meji tí ó wà ninu ilé OLUWA. Ó fọ́ gbogbo wọn túútúú, ó sì kó wọn dà sí àfonífojì Kidironi.

13 Josaya wó gbogbo ibi gíga tí wọn tún ń pè ní òkè ìdíbàjẹ́, tí Solomoni kọ́ sí apá ìhà ìlà oòrùn Jerusalẹmu, ní ìhà gúsù Òkè Olifi, fún àwọn oriṣa Aṣitoreti, ohun ìríra àwọn ará Sidoni, ati Kemoṣi, ohun ìríra àwọn ará Moabu, ati fún Milikomu, ohun ìríra àwọn ará Amoni.

14 Josaya ọba fọ́ àwọn òpó òkúta túútúú, ó gé àwọn ère oriṣa Aṣera, ó sì kó egungun eniyan sí ibi tí wọ́n ti hú wọn jáde.

15 Josaya wó ilé oriṣa tí Jeroboamu ọba, ọmọ Nebati, ẹni tí ó mú Israẹli ṣẹ̀, kọ́ sí Bẹtẹli. Josaya wó pẹpẹ ìrúbọ tí ó wà níbẹ̀, ó fọ́ òkúta rẹ̀ túútúú, ó lọ̀ wọ́n lúbúlúbú, ó sì jó ère Aṣera pẹlu.

16 Bí Josaya ti yí ojú pada, ó rí àwọn ibojì kan lórí òkè. Ó bá pàṣẹ pé kí wọ́n kó àwọn egungun inú wọn jáde, kí wọ́n sì jó wọn lórí pẹpẹ ìrúbọ náà; ó sì fi bẹ́ẹ̀ sọ pẹpẹ ìrúbọ náà di ìbàjẹ́, gẹ́gẹ́ bí àsọtẹ́lẹ̀ tí wolii Ọlọrun ti sọ. Nígbà tí Josaya ọba rí ibojì wolii tí ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ náà,

17 ó bèèrè pé, “Ọ̀wọ̀n ibojì ta ni mò ń wò lọ́ọ̀ọ́kán yìí?”

Àwọn tí wọ́n wà ní Bẹtẹli sì dáhùn pé, “Ibojì wolii tí ó wá láti Juda tí ó sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ àwọn ohun tí ò ń ṣe sí pẹpẹ ìrúbọ yìí ni.”

18 Josaya bá pàṣẹ pé kí wọ́n fi sílẹ̀ bí ó ti wà, kí wọ́n má ṣe kó egungun rẹ̀.

Nítorí náà, wọn kò kó egungun rẹ̀ ati egungun wolii tí ó wá láti Samaria.

19 Ní gbogbo àwọn ìlú Israẹli ni Josaya ti wó àwọn ilé oriṣa tí àwọn ọba Israẹli kọ́ tí ó bí OLUWA ninu. Bí ó ti ṣe pẹpẹ ìrúbọ tí ó wà ní Bẹtẹli ni ó ṣe àwọn pẹpẹ ìrúbọ náà.

20 Ó pa gbogbo àwọn alufaa ibi ìrúbọ lórí pẹpẹ ìrúbọ wọn, ó sì jó egungun eniyan lórí gbogbo àwọn pẹpẹ ìrúbọ náà. Lẹ́yìn náà, ó pada sí Jerusalẹmu.

Josaya Ọba ṣe Àjọ̀dún Àjọ Ìrékọjá

21 Josaya pàṣẹ pé kí àwọn eniyan náà ṣe Àjọ̀dún Àjọ Ìrékọjá fún ògo OLUWA Ọlọrun wọn, gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ninu ìwé majẹmu;

22 nítorí pé wọn kò ti ṣe Àjọ̀dún Àjọ Ìrékọjá mọ́ láti àkókò àwọn onídàájọ́ ati ti àwọn ọba Israẹli ati Juda.

23 Ṣugbọn ní ọdún kejidinlogun tí Josaya ti jọba ni àwọn eniyan ṣe Àjọ̀dún Àjọ Ìrékọjá fún ògo OLUWA ní Jerusalẹmu.

Àwọn Àtúnṣe Mìíràn tí Josaya Ṣe

24 Josaya ọba lé gbogbo àwọn abókùúsọ̀rọ̀ ati àwọn oṣó jáde kúrò ní Jerusalẹmu, ó sì kó àwọn ère, àwọn oriṣa, ati gbogbo ohun ìbọ̀rìṣà kúrò ní Jerusalẹmu ati ilẹ̀ Juda, gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ninu òfin tí ó wà ninu ìwé tí Hilikaya olórí alufaa rí ninu ilé OLUWA.

25 Ṣáájú Josaya ati lẹ́yìn rẹ̀, kò sí ọba kankan tí ó fi gbogbo ọkàn rẹ̀, gbogbo ẹ̀mí rẹ̀ ati gbogbo agbára rẹ̀ sin Ọlọrun, gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ninu gbogbo òfin Mose.

26 Ṣugbọn sibẹsibẹ ibinu gbígbóná OLUWA tí ó ti ru sókè sí Juda nítorí ìwà burúkú Manase kò rọlẹ̀.

27 OLUWA sọ pé, “N óo ṣe ohun tí mo ṣe sí Israẹli sí Juda, n óo pa àwọn eniyan Juda run, n óo sì kọ Jerusalẹmu, ìlú tí mo yàn sílẹ̀, ati ilé OLUWA tí mo yàn fún ìsìn mi.”

Ìgbẹ̀yìn Ìjọba Josaya

28 Gbogbo nǹkan yòókù tí Josaya ṣe ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Juda.

29 Ní àkókò tí Josaya jọba ni Neko, ọba Ijipti kó ogun rẹ̀ wá sí etí odò Yufurate láti ran ọba Asiria lọ́wọ́. Josaya pinnu láti dá ogun Ijipti pada ní Megido, ṣugbọn ó kú lójú ogun náà.

30 Àwọn olórí ogun rẹ̀ gbé òkú rẹ̀ sinu kẹ̀kẹ́ ogun kan láti Megido wọn gbé e wá sí Jerusalẹmu, wọ́n sì sin ín sinu ibojì rẹ̀.

Àwọn eniyan Juda sì fi òróró yan Jehoahasi ọmọ rẹ̀ ní ọba.

Jehoahasi, Ọba Juda

31 Ẹni ọdún mẹtalelogun ni Jehoahasi nígbà tí ó jọba ó sì wà lórí oyè ní Jerusalẹmu fún oṣù mẹta. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Hamutali, ọmọ Jeremaya, ará Libina.

32 Òun náà ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA, ó tẹ̀lé ìwà ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba ńlá rẹ̀.

33 Neko ọba Ijipti mú Jehoahasi ní ìgbèkùn ní Ribila ní ilẹ̀ Hamati, kí ó má baà jọba lórí Jerusalẹmu mọ́. Ó sì mú kí Juda san ọgọrun-un (100) ìwọ̀n talẹnti fadaka ati ìwọ̀n talẹnti wúrà kan bí ìṣákọ́lẹ̀.

34 Neko sì fi Eliakimu, ọmọ Josaya, jọba dípò rẹ̀, ṣugbọn ó yí orúkọ rẹ̀ pada sí Jehoiakimu. Neko mú Jehoahasi lọ sí Ijipti, ibẹ̀ ni ó sì kú sí.

Jehoiakimu Ọba Juda

35 Jehoiakimu ọba gba owó orí lọ́wọ́ àwọn eniyan gẹ́gẹ́ bí ọrọ̀ wọn ti pọ̀ tó, láti rí owó san ìṣákọ́lẹ̀ fún ọba Ijipti gẹ́gẹ́ bí ó ti pa á láṣẹ fún un.

36 Jehoiakimu jẹ́ ẹni ọdún mẹẹdọgbọn nígbà tí ó jọba, ó sì jọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mọkanla. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Sebida, ọmọ Pedaaya, láti ìlú Ruma.

37 Ó ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA, ó tẹ̀lé ìwà ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba ńlá rẹ̀.

Categories
ÀWỌN ỌBA KEJI

ÀWỌN ỌBA KEJI 24

1 Ní àkókò ìjọba Jehoiakimu ni Nebukadinesari, ọba Babiloni gbógun ti Jerusalẹmu, Jehoiakimu sì di iranṣẹ rẹ̀ fún ọdún mẹta. Lẹ́yìn náà, ó pada lẹ́yìn Nebukadinesari, ó sì ṣọ̀tẹ̀ sí i.

2 OLUWA bá rán àwọn ọmọ ogun Kalidea, ati ti Siria, ti Moabu, ati ti Amoni, láti pa Juda run bí ọ̀rọ̀ ti OLUWA sọ láti ẹnu àwọn wolii, iranṣẹ rẹ̀.

3 Ìjìyà yìí dé bá Juda láti ọ̀dọ̀ OLUWA, láti pa wọ́n run kúrò níwájú rẹ̀, nítorí ìwà ẹ̀ṣẹ̀ Manase ọba,

4 ati nítorí ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ tí ó ti ta sílẹ̀, nítorí tí ó ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ ní gbogbo ìgboro Jerusalẹmu, OLUWA kò ní dáríjì í.

5 Gbogbo nǹkan yòókù tí Jehoiakimu ṣe ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Juda.

6 Jehoiakimu kú, Jehoiakini ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀.

7 Ọba Ijipti kò lè jáde kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀ mọ́, nítorí pé ọba Babiloni ti gba gbogbo ilẹ̀ ọba Ijipti láti odò Ijipti títí dé odò Yufurate.

Jehoiakini, Ọba Juda

8 Ẹni ọdún mejidinlogun ni Jehoiakini nígbà tí ó jọba, ó sì wà lórí oyè ní Jerusalẹmu fún oṣù mẹta. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Nehuṣita, ọmọ Elinatani ará Jerusalẹmu.

9 Òun náà ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA gẹ́gẹ́ bíi baba rẹ̀.

10 Ní àkókò náà ni àwọn ọmọ ogun Nebukadinesari, ọba Babiloni, lọ gbógun ti Jerusalẹmu, wọ́n sì dó tì í.

11 Ní àkókò tí wọ́n dó ti ìlú náà ni Nebukadinesari ọba Babiloni lọ sibẹ.

12 Ní ọdún kẹjọ tí ọba Babiloni jọba ni Jehoiakini ọba Juda jọ̀wọ́ ara rẹ̀ sílẹ̀ fún ọba Babiloni, ó sì jọ̀wọ́ ìyá rẹ̀, àwọn iranṣẹ rẹ̀, àwọn ìjòyè rẹ̀ ati àwọn òṣìṣẹ́ ààfin rẹ̀ pẹlu, ọba Babiloni bá kó wọn ní ìgbèkùn.

13 Ó kó gbogbo àwọn ìṣúra ilé OLUWA ati àwọn ìṣúra tí ó wà ní ààfin. Gbogbo ohun èèlò wúrà tí wọ́n wà ninu ilé OLUWA, tí Solomoni ọba Israẹli ṣe, ni ó gé sí wẹ́wẹ́, gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti sọ tẹ́lẹ̀.

14 Ó kó gbogbo Jerusalẹmu ní ìgbèkùn; gbogbo àwọn ìjòyè, àwọn akọni, àwọn oníṣẹ́ ọwọ́, ati àwọn alágbẹ̀dẹ, gbogbo wọn jẹ́ ẹgbaarun (10,000), kò ṣẹ́ku ẹyọ ẹnìkan ní ìlú náà, àfi àwọn talaka.

15 Ó kó ọba Jehoiakini, ati ìyá rẹ̀, ati àwọn aya rẹ̀, àwọn ìwẹ̀fà rẹ̀ ati àwọn ìjòyè ilẹ̀ náà ní ìgbèkùn láti Jerusalẹmu lọ sí Babiloni.

16 Ọba Babiloni kó ẹẹdẹgbaarin (7,000) àwọn akọni ní ìgbèkùn ati ẹgbẹrun kan (1,000) àwọn oníṣẹ́ ọwọ́ ati alágbẹ̀dẹ, gbogbo wọn jẹ́ alágbára tí wọ́n lè jagun.

17 Ó fi Matanaya, arakunrin Jehoiakini jọba dípò rẹ̀, ó sì yí orúkọ rẹ̀ pada sí Sedekaya.

Sedekaya, Ọba Juda

18 Ẹni ọdún mọkanlelogun ni Sedekaya nígbà tí ó wà lórí oyè, ó sì jọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mọkanla. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Hamutali, ọmọ Jeremaya ará Libina.

19 Ó ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA, ó tẹ̀lé ìwà ẹ̀ṣẹ̀ Jehoiakimu baba rẹ̀.

20 Nítorí náà, OLUWA bínú sí Jerusalẹmu ati Juda; ó sì lé wọn kúrò níwájú rẹ̀.

Sedekaya sì ṣọ̀tẹ̀ sí ọba Babiloni.

Categories
ÀWỌN ỌBA KEJI

ÀWỌN ỌBA KEJI 25

Ìṣubú Jerusalẹmu

1 Ní ọjọ́ kẹwaa oṣù kẹwaa ọdún kẹsan-an ìjọba rẹ̀, Nebukadinesari, ọba Babiloni, òun ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ gbógun ti Jerusalẹmu, wọ́n dó tì í, wọ́n sì mọ odi yí i ká.

2 Wọ́n dó ti ìlú náà títí di ọdún kọkanla ìjọba Sedekaya.

3 Ní ọjọ́ kẹsan-an oṣù kẹrin, ìyàn náà mú láàrin ìlú tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn eniyan kò fi rí oúnjẹ jẹ mọ́.

4 Nígbà náà ni wọ́n lu odi ìlú náà, ọba ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sì gba ibẹ̀ sá jáde lóru. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ará Kalidea yí ìlú náà po, wọ́n lu odi ìlú náà, wọ́n gba ẹnu ọ̀nà tí ó wà láàrin odi mejeeji lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọgbà ọba, wọ́n sì gba ọ̀nà tí ó lọ sí Araba.

5 Ṣugbọn àwọn ọmọ ogun Kalidea lépa Sedekaya, wọ́n bá a ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jẹriko, gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sì túká kúrò lẹ́yìn rẹ̀.

6 Ọwọ́ wọn tẹ Sedekaya, wọ́n bá mú un lọ sọ́dọ̀ ọba Babiloni ní Ribila, ó sì dá ẹjọ́ fún un.

7 Wọ́n pa àwọn ọmọ Sedekaya lójú rẹ̀, lẹ́yìn náà ni Nebukadinesari ọba yọ ojú Sedekaya, ó fi ẹ̀wọ̀n dè é, ó sì mú un lọ sí Babiloni.

Pípa Tẹmpili Run

8 Ní ọjọ́ keje oṣù karun-un ọdún kọkandinlogun ìjọba Nebukadinesari, ọba Babiloni, Nebusaradani, tí ń ṣiṣẹ́ fún ọba Babiloni, tí ó sì tún jẹ́ olórí àwọn tí ń ṣọ́ Babiloni wá sí Jerusalẹmu.

9 Ó sun ilé OLUWA níná, ati ilé ọba ati gbogbo ilé tí ó wà ní Jerusalẹmu. Gbogbo àwọn ilé ńláńlá tí ó wà níbẹ̀ ni ó sì dáná sun.

10 Gbogbo àwọn ọmọ ogun Kalidea, tí wọ́n wà pẹlu olórí àwọn tí wọn ń ṣọ́ ọba wó gbogbo odi Jerusalẹmu lulẹ̀ patapata.

11 Nebusaradani kó àwọn tí wọ́n kù láàrin ìlú ati àwọn tí wọ́n sá tọ ọba Babiloni lọ, pẹlu ogunlọ́gọ̀ àwọn yòókù lọ sí ìgbèkùn.

12 Ṣugbọn ó fi díẹ̀ ninu àwọn talaka sílẹ̀ láti máa tọ́jú ọgbà àjàrà ati láti máa dáko.

13 Àwọn ọmọ ogun Kalidea fọ́ àwọn òpó bàbà tí ó wà ninu ilé OLUWA ati agbada bàbà ńlá tí ó wà ninu ilé OLUWA pẹlu ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀, wọ́n fọ́ wọn sí wẹ́wẹ́, wọ́n sì kó gbogbo bàbà wọn lọ sí Babiloni.

14 Wọ́n kó àwọn ìkòkò, àwọn ọ̀kọ̀, àwọn ọ̀pá tí wọ́n fi ń pa iná lẹ́nu àtùpà, àwọn àwo turari ati àwọn ohun èlò bàbà tí wọ́n máa ń lò fún ìsìn ninu ilé OLUWA.

15 Bákan náà, wọ́n kó àwọn àwo ìfọnná, ati àwọn àwo kòtò, gbogbo ohun tí ó jẹ́ ti wúrà ati fadaka, ni olórí àwọn tí wọn ń ṣọ́ ọba Babiloni kó lọ.

16 Bàbà tí Solomoni fi ṣe àwọn òpó mejeeji, agbada omi ati ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀ kọjá wíwọ̀n.

17 Gíga ọ̀kan ninu àwọn òpó náà jẹ́ igbọnwọ mejidinlogun, ọpọ́n idẹ tí ó wà lórí rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ mẹta, wọ́n fi bàbà ṣe ẹ̀wọ̀n bí ẹ̀gbà ọrùn ati pomegiranate yí ọpọ́n náà ká, òpó keji sì dàbí ti àkọ́kọ́ pẹlu ẹ̀wọ̀n bàbà náà.

A Kó Àwọn Eniyan Juda Lọ sí Babiloni

18 Olórí àwọn tí wọn ń ṣọ́ ọba Babiloni mú Seraya olórí alufaa, ati Sefanaya igbákejì alufaa, ati àwọn aṣọ́nà mẹta.

19 Ó sì mú ọ̀gágun tí ń ṣe àkóso àwọn ọmọ ogun ní ìlú ati àwọn aṣojú ọba marun-un tí ó rí ninu ìlú ati akọ̀wé olórí ogun, tí ń kọ orúkọ àwọn eniyan ilẹ̀ náà sílẹ̀ fún ogun jíjà, ati ọgọta ọkunrin tí ó rí ninu ìlú náà.

20 Nebusaradani kó gbogbo wọn lọ sí ọ̀dọ̀ ọba Babiloni ní Ribila.

21 Ọba Babiloni lù wọ́n, ó sì pa wọ́n sórí ilẹ̀ Hamati.

Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ṣe kó Juda ní ìgbèkùn kúrò lórí ilẹ̀ rẹ̀.

Gedalaya, Gomina Juda

22 Nebukadinesari ọba Babiloni yan Gedalaya ọmọ Ahikamu, ọmọ Ṣafani ní gomina lórí àwọn tí wọ́n kù ní ilẹ̀ Juda.

23 Nígbà tí àwọn olórí ogun tí wọ́n wà ní ìgbèríko pẹlu àwọn ọmọ ogun wọn gbọ́ pé ọba Babiloni ti fi Gedalaya ọmọ Ahikamu ṣe Gomina ní ilẹ̀ Juda, àwọn pẹlu àwọn eniyan wọn wá sí ọ̀dọ̀ Gedalaya ní Misipa. Àwọn tí wọ́n wá ni Iṣimaeli, ọmọ Netanaya, Johanani, ọmọ Karea, Seraya, ọmọ Tanhumeti, ará Netofa, ati Jaasanaya, ọmọ ará Maakati.

24 Gedalaya bá búra fún wọn, ó ní: “Ẹ má ṣe bẹ̀rù nítorí àwọn olórí Kalidea, ẹ máa gbé ilẹ̀ náà kí ẹ sì máa sin ọba Babiloni, yóo sì dára fun yín.”

25 Ṣugbọn ní oṣù keje Iṣimaeli, ọmọ Netanaya, ọmọ Eliṣama, láti ìdílé ọba, pẹlu àwọn ọkunrin mẹ́wàá dojú kọ Gedalaya, wọ́n sì pa òun, ati àwọn Juu ati àwọn ará Kalidea tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ ní Misipa.

26 Ni gbogbo wọn, àtọmọdé, àtàgbà, ati àwọn olórí ogun bá gbéra, wọ́n kó lọ sí Ijipti, nítorí ẹ̀rù àwọn ará Kalidea bà wọ́n.

A Dá Jehoiakini Sílẹ̀ kúrò Ní Ọgbà Ẹ̀wọ̀n

27 Ní ọdún kẹtadinlogoji lẹ́yìn tí wọ́n ti mú Jehoiakini ọba Juda lọ sí ìgbèkùn, ní ọjọ́ kẹtadinlọgbọn oṣù kejila ọdún náà, Efilimerodaki, ọba Babiloni, gbé ọ̀rọ̀ Jehoiakini yẹ̀wò, ní ọdún tí ó gorí oyè, ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n tú u sílẹ̀ kúrò ní ẹ̀wọ̀n.

28 Ó bá a sọ̀rọ̀ rere, ó sì fi sí ipò tí ó ga ju ti gbogbo àwọn ọba tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ ní Babiloni lọ.

29 Jehoiakini bọ́ aṣọ ẹ̀wọ̀n kúrò lọ́rùn, ó sì ń bá ọba jẹun lórí tabili ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.

30 Ọba Babiloni rí i pé òun ń pèsè ohun tí ó nílò ní ojoojumọ fún un, títí di ọjọ́ ikú rẹ̀.