Categories
ÀWỌN ỌBA KEJI

ÀWỌN ỌBA KEJI Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Àwọn Ìtàn inú ìwé yìí jẹ́ àfikún ti inú

Ìwé Àwọn Ọba Kinni

, nípa ìjọba ìpínfẹ̀ àwọn ẹ̀yà Israẹli, ti àríwá ati ti gúsù. Ọ̀nà meji pataki ni a lè pín ìtàn inú ìwé yìí sí: (1) Ìtàn ìjọba ìpínlẹ̀ mejeeji láti nǹkan bíi ààrin sẹntiuri kẹsan-an (9th Century B.C.), kí á tó bí OLUWA wa títí di àkókò ìṣubú Samaria ati òpin ìjọba ìpínlẹ̀ àríwá ní ẹẹdẹgbẹrin ó lé mejilelogun ọdún (722 B.C.) kí á tó bí OLUWA wa. (2) Ìtàn ìjọba ìpínlẹ̀ Juda láti àkókò ìṣubú ìjọba ìpínlẹ̀ Israẹli títí di ìgbà tí Nebukadinesari ọba Babiloni kó Jerusalẹmu nígbèkùn, tí ó sì pa á run ní ọrinlelẹẹdẹgbẹta ó lé mẹfa ọdún (586 B.C.) kí á tó bí OLUWA wa. Ní òpin ìtàn inú ìwé náà, a rí ìtàn Gedalaya gomina Juda lábẹ́ àṣẹ àwọn ará Babiloni ati àkọsílẹ̀ bí wọ́n ṣe dá Jehoiakimu ọba Juda sílẹ̀ ní ẹ̀wọ̀n ní Babiloni.

Àwọn ìdàrúdàpọ̀ wọnyi dé bá àwọn ọba ati àwọn ọmọ Israẹli ati Juda nítorí aiṣododo wọn. Ohun ìyanu ni àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọnyi jẹ́ ninu ìtàn àwọn ọmọ Israẹli.

Ipa pataki ni Wolii Eliṣa tí ó jẹ́ ọmọlẹ́yìn Wolii Elija kó ninu àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ inú ìwé Àwọn Ọba Keji.

Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí

Orílẹ̀-èdè Israẹli pín sí meji 1:1–17:41

a. Wolii Eliṣa 1:1–8:15

b. Àwọn Ọba Juda ati Àwọn Ọba Israẹli 8:16–17:4

d. Ìṣubú Samaria 17:5-41

Ìjọba ìpínlẹ̀ Juda 18:1–25:30

a. Láti orí Hesekaya dé Josaya 18:1–21:26

b. Ìjọba Josaya 22:1–23:30

d. Àwọn ọba tí wọ́n jẹ kẹ́yìn ní Juda 23:31–24:20

e. Ìṣubú Jerusalẹmu 25:1-30

Categories
ÀWỌN ỌBA KEJI

ÀWỌN ỌBA KEJI 1

Elija ati Ọba Ahasaya

1 Lẹ́yìn ikú Ahabu ọba, àwọn ará Moabu ṣọ̀tẹ̀ sí Israẹli, wọ́n fẹ́ fi tipátipá gba òmìnira.

2 Ahasaya ọba ṣubú láti orí òkè ilé rẹ̀ ní Samaria, ó sì farapa pupọ. Nítorí náà ni ó ṣe rán oníṣẹ́ lọ bèèrè lọ́wọ́ Baalisebubu, oriṣa Ekironi, bóyá òun yóo sàn ninu àìsàn náà tabi òun kò ní sàn.

3 Ṣugbọn angẹli OLUWA kan pàṣẹ fún wolii Elija, ará Tiṣibe pé, “Lọ pàdé àwọn oníṣẹ́ ọba Samaria, kí o sì bèèrè lọ́wọ́ wọn pé, ‘Ṣé nítorí pé kò sí Ọlọrun ní Israẹli ni ẹ fi ń lọ wádìí nǹkan lọ́dọ̀ Baalisebubu, oriṣa Ekironi?’

4 Ẹ lọ sọ fún ọba pé, báyìí ni OLUWA wí, ‘O kò ní sàn ninu àìsàn náà, kíkú ni o óo kú.’ ”

Elija sì ṣe gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún un.

5 Àwọn oníṣẹ́ náà pada sọ́dọ̀ ọba, ọba bá bèèrè pé, “Kí ló dé tí ẹ fi pada?”

6 Wọ́n dáhùn pé, “Ọkunrin kan pàdé wa lọ́nà, ó sì sọ fún wa pé, ‘Ẹ pada sọ́dọ̀ ọba tí ó ran yín, kí ẹ sì sọ fún un pé, “OLUWA ní, ṣé nítorí pé kò sí Ọlọrun ní Israẹli ni o fi rán oníṣẹ́ lọ wádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ Baalisebubu, oriṣa Ekironi? Nítorí náà o kò ní sàn ninu àìsàn yìí, o óo kú ni.” ’ ”

7 Ọba bá bèèrè pé, “Irú ọkunrin wo ni ó wá pàdé yín lójú ọ̀nà, tí ó sọ bẹ́ẹ̀ fun yín?”

8 Wọ́n dáhùn pé, “Ọkunrin náà wọ aṣọ tí wọ́n fi awọ ẹranko ṣe, ó sì di àmùrè awọ mọ́ ẹ̀gbẹ́.”

Ọba dáhùn pé, “Elija ará Tiṣibe ni.”

9 Ọba bá rán ọ̀gágun kan ati àwọn aadọta ọmọ ogun rẹ̀ kí wọ́n lọ mú Elija. Ọ̀gágun náà rí Elija níbi tí ó jókòó sí ní téńté òkè, ó sì wí fún un pé, “Ìwọ eniyan Ọlọrun, ọba sọ pé kí o sọ̀kalẹ̀ wá.”

10 Elija sì dáhùn pé, “Bí mo bá jẹ́ eniyan Ọlọrun, kí iná wá láti ọ̀run, kí ó sì jó ìwọ ati àwọn aadọta ọmọ ogun rẹ!” Lẹ́sẹ̀kan náà, iná wá láti ọ̀run, ó sì jó ọ̀gágun náà ati gbogbo àwọn ọmọ-ogun rẹ̀.

11 Ọba bá tún rán ọ̀gágun mìíràn ati àwọn aadọta ọmọ-ogun rẹ̀ láti lọ mú Elija. Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ Elija òun náà tún sọ fún un pé, “Ìwọ eniyan Ọlọrun, ọba sọ pé kí o sọ̀kalẹ̀ wá kíákíá.”

12 Elija tún dáhùn pé, “Bí mo bá jẹ́ eniyan Ọlọrun, kí iná wá láti ọ̀run, kí ó sì jó ìwọ ati àwọn aadọta ọmọ ogun rẹ!” Lẹ́sẹ̀ kan náà, iná wá láti ọ̀run, ó sì jó ọ̀gágun náà ati gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀.

13 Lẹ́ẹ̀kan sí i, ọba rán ọ̀gágun mìíràn ati àwọn aadọta ọmọ ogun rẹ̀. Ṣugbọn ó gòkè lọ sọ́dọ̀ Elija, ó sì kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀, ó bẹ̀ ẹ́ pé, “Ìwọ eniyan Ọlọrun jọ̀wọ́ mo bẹ̀ ọ́, ṣàánú fún mi ati fún àwọn iranṣẹ rẹ wọnyi, kí o sì dá ẹ̀mí wa sí.

14 Iná tí ó wá láti ọ̀run ni ó pa àwọn ọ̀gágun meji ti iṣaaju ati àwọn ọmọ ogun wọn, nítorí náà mo bẹ̀ ọ́, dá ẹ̀mí mi sí.”

15 Nígbà náà ni angẹli OLUWA sọ fún Elija pé kí ó bá wọn lọ, kí ó má sì bẹ̀rù. Elija bá bá a lọ sọ́dọ̀ ọba.

16 Elija sọ fún ọba pé, báyìí ni OLUWA wí, “Nítorí pé o rán oníṣẹ́ láti lọ wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ Baalisebubu, oriṣa Ekironi, bí ẹni pé kò sí Ọlọrun ní Israẹli láti wádìí lọ́wọ́ rẹ̀, nítorí náà, o kò ní sàn ninu àìsàn yìí, kíkú ni o óo kú.”

17 Ahasaya sì kú gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ OLUWA tí Elija sọ. Ṣugbọn nítorí pé kò ní ọmọkunrin kankan Joramu, arakunrin rẹ̀ jọba lẹ́yìn rẹ̀, ní ọdún keji tí Jehoramu ọmọ Jehoṣafati jọba ní Juda.

18 Gbogbo nǹkan yòókù tí Ahasaya ṣe ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli.

Categories
ÀWỌN ỌBA KEJI

ÀWỌN ỌBA KEJI 2

A Gbé Elija Lọ Sọ́run

1 Nígbà tí àkókò tó fún OLUWA láti fi ààjà gbé Elija lọ sí ọ̀run, Elija ati Eliṣa kúrò ní Giligali.

2 Elija sọ fún Eliṣa pé, “Dúró níhìn-ín nítorí pé OLUWA rán mi sí Bẹtẹli.”

Ṣugbọn Eliṣa dáhùn pé, “Bí OLUWA ti wà láàyè tí ìwọ náà sì wà láàyè, n kò ní fi ọ́ sílẹ̀.” Nítorí náà wọ́n jọ lọ sí Bẹtẹli.

3 Àwọn ọmọ wolii tí wọn ń gbé Bẹtẹli tọ Eliṣa wá, wọ́n bi í pé, “Ǹjẹ́ o mọ̀ pé OLUWA yóo mú ọ̀gá rẹ lọ lónìí?”

Eliṣa dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, mo mọ̀, ṣugbọn ẹ má ṣe sọ ohunkohun nípa rẹ̀.”

4 Elija tún sọ fún Eliṣa pé, “Dúró níhìn-ín, nítorí pé OLUWA rán mi sí Jẹriko.”

Eliṣa dáhùn pé, “Bí OLUWA ti wà láàyè, tí ìwọ náà sì wà láàyè, n kò ní fi ọ́ sílẹ̀.” Nítorí náà wọ́n jọ lọ sí Jẹriko.

5 Àwọn ọmọ wolii tí wọn ń gbé Jẹriko tọ Eliṣa wá, wọ́n sì bi í pé, “Ǹjẹ́ o mọ̀ pé OLUWA yóo mú ọ̀gá rẹ lọ lónìí?”

Eliṣa dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, mo mọ̀, ṣugbọn ẹ má ṣe sọ ohunkohun nípa rẹ̀.”

6 Elija tún sọ fún Eliṣa pé, “Dúró níhìn-ín nítorí pé OLUWA rán mi sí odò Jọdani.”

Eliṣa dáhùn pé, “Bí OLUWA ti ń bẹ, tí ìwọ náà sì wà láàyè, n kò ní fi ọ́ sílẹ̀.” Nítorí náà wọ́n jọ ń lọ.

7 Aadọta ninu àwọn ọmọ àwọn wolii náà sì dúró ní òkèèrè, wọ́n ń wò wọ́n. Elija ati Eliṣa sì dúró létí odò Jọdani.

8 Elija bọ́ aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀, ó fi lu odò náà, odò sì pín sí meji títí tí Elija ati Eliṣa fi kọjá sí òdìkejì odò lórí ìyàngbẹ ilẹ̀.

9 Níbẹ̀ ni Elija ti bèèrè lọ́wọ́ Eliṣa pé, “Kí ni o fẹ́ kí n ṣe fún ọ kí á tó gbé mi kúrò lọ́dọ̀ rẹ.”

Eliṣa sì dáhùn pé, “Mo bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí ìlọ́po meji agbára rẹ bà lé mi.”

10 Elija dáhùn pé, “Ohun tí o bèèrè yìí ṣòro, ṣugbọn bí o bá rí mi nígbà tí wọ́n bá ń gbé mi lọ, o óo rí ohun tí o bèèrè gbà. Ṣugbọn bí o kò bá rí mi, o kò ní rí i gbà.”

11 Bí wọ́n ti ń lọ tí wọ́n sì ń sọ̀rọ̀, lójijì kẹ̀kẹ́-ogun iná ati ẹṣin iná gba ààrin wọn kọjá, Elija sì bá ààjà gòkè lọ sí ọ̀run.

12 Bí Eliṣa ti rí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, ó kígbe pe Elija, ó ní, “Baba mi, baba mi, kẹ̀kẹ́-ogun Israẹli ati àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀.” Kò rí Elija mọ́, ó bá fa aṣọ rẹ̀ ya sí meji láti fi ìbànújẹ́ rẹ̀ hàn.

13 Lẹ́yìn náà ó mú aṣọ àwọ̀lékè Elija tí ó bọ́ sílẹ̀, ó sì pada lọ dúró ní etí odò Jọdani.

14 Ó fi aṣọ àwọ̀lékè tí ó já bọ́ sílẹ̀ lára Elija lu odò, ó sì kígbe pé, “Níbo ni OLUWA Ọlọrun Elija wà?” Lẹ́yìn náà odò pín sí meji, Eliṣa bá kọjá sí òdìkejì.

15 Nígbà tí àwọn ọmọ àwọn wolii tí wọ́n wà ní Jẹriko rí i, wọ́n ní, “Ẹ̀mí Elija ti wà lára Eliṣa!” Wọ́n lọ pàdé rẹ̀, wọ́n wólẹ̀ níwájú rẹ̀,

16 wọ́n ní, “Aadọta ọkunrin alágbára wà pẹlu àwa iranṣẹ rẹ, jọ́wọ́ jẹ́ kí wọ́n lọ wá ọ̀gá rẹ, bóyá Ẹ̀mí OLUWA tí ó gbé e lọ ti jù ú sílẹ̀ ní orí ọ̀kan ninu àwọn òkè agbègbè yìí, tabi ninu àfonífojì kan.”

Eliṣa sì dá wọn lóhùn pé, “Ẹ má ṣe rán wọn lọ.”

17 Ṣugbọn wọ́n rọ̀ ọ́ títí tí ojú fi ń tì í, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ rán wọn lọ.” Wọ́n bá rán àwọn aadọta ọkunrin lọ, wọ́n wá Elija ní àwọn orí òkè ati àwọn àfonífojì fún ọjọ́ mẹta, ṣugbọn wọn kò rí i.

18 Wọ́n pada wá jábọ̀ fún Eliṣa ní Jẹriko, ó sì wí fún wọn pé, “Ṣebí mo ti sọ fun yín pé kí ẹ má lọ?”

Àwọn Iṣẹ́ Ìyanu Eliṣa

19 Àwọn ọkunrin ìlú náà wá sọ́dọ̀ Eliṣa, wọ́n sọ fún un pé, “Ìlú yìí dára gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin náà ti mọ̀, ṣugbọn omi tí à ń mu kò dára, bẹ́ẹ̀ ni ilẹ̀ náà sì jẹ́ aṣálẹ̀.”

20 Eliṣa bá dá wọn lóhùn pé, “Ẹ bu iyọ̀ sinu abọ́ tuntun, kí ẹ sì gbé e wá fún mi.” Wọ́n bá ṣe bí ó ti wí.

21 Lẹ́yìn náà, ó jáde lọ sí ibi orísun omi náà, ó da iyọ̀ náà sí i, ó sì wí pé, “Báyìí ni OLUWA wí, ‘Mo sọ omi yìí di ọ̀tun lónìí, kò ní fa ikú mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò ní ba oyún jẹ́ mọ́.’ ”

22 Láti ìgbà náà ni omi náà ti dára títí di òní olónìí gẹ́gẹ́ bí Eliṣa ti sọ.

23 Eliṣa kúrò níbẹ̀, ó lọ sí Bẹtẹli. Bí ó ti ń lọ, àwọn ọmọdekunrin kan ní ìlú náà bẹ̀rẹ̀ sí fi Eliṣa ṣe ẹlẹ́yà; wọ́n ń wí pé, “Kúrò níbí, ìwọ apárí! Kúrò níbí, ìwọ apárí!”

24 Nígbà tí ó yí ojú pada, tí ó rí wọn, ó ṣépè lé wọn ní orúkọ OLUWA, abo ẹranko beari meji sì jáde láti inú igbó, wọ́n fa mejilelogoji ninu àwọn ọmọ náà ya.

25 Eliṣa sì lọ sí òkè Kamẹli, láti ibẹ̀, ó lọ sí Samaria.

Categories
ÀWỌN ỌBA KEJI

ÀWỌN ỌBA KEJI 3

Ogun láàrin Israẹli ati Moabu

1 Ní ọdún kejidinlogun tí Jehoṣafati jọba ní Juda, Joramu, ọmọ Ahabu, jọba lórí Israẹli ní Samaria. Ó sì wà lórí oyè fún ọdún mejila.

2 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, ó dẹ́ṣẹ̀ sí OLUWA, ṣugbọn ó wó òpó oriṣa Baali tí Baba rẹ̀ mọ, ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ kò sì pọ̀ tó ti baba rẹ̀ tabi ti Jesebẹli ìyá rẹ̀.

3 Ó mú kí Israẹli dẹ́ṣẹ̀ lọpọlọpọ gẹ́gẹ́ bíi Jeroboamu, tí ó ti jọba ṣáájú kò sì ronupiwada.

4 Meṣa, ọba Moabu, a máa sin aguntan; ní ọdọọdún, a máa fún ọba Israẹli ní ọ̀kẹ́ marun-un (100,000) ọ̀dọ́ aguntan ati irun ọ̀kẹ́ marun-un (100,000) àgbò, gẹ́gẹ́ bí ìṣákọ́lẹ̀.

5 Ṣugbọn lẹ́yìn tí Ahabu kú, ọba Moabu ṣọ̀tẹ̀, kò san ìṣákọ́lẹ̀ náà fún ọba Israẹli mọ́.

6 Joramu ọba bá gbéra ní Samaria, ó sì kó gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jọ.

7 Ó ranṣẹ sí Jehoṣafati ọba Juda pé, “Ọba Moabu ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi, ṣé o óo bá mi lọ láti bá a jagun?”

Jehoṣafati dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, n óo lọ, ìwọ ni o ni mí, ìwọ ni o sì ni àwọn ọmọ ogun mi ati àwọn ẹṣin mi pẹlu.”

8 Jehoṣafati bèèrè pé, “Ọ̀nà wo ni a óo gbà lọ?”

Joramu sì dáhùn pé, “Ọ̀nà aṣálẹ̀ Edomu ni.”

9 Ni Joramu, ati ọba Juda ati ọba Edomu bá gbéra láti lọ sójú ogun. Lẹ́yìn tí wọ́n ti rìn fún ọjọ́ meje, kò sí omi mímu mọ́ fún wọn ati fún àwọn ẹranko tí wọ́n ru ẹrù wọn.

10 Joramu ọba ní, “Ó mà ṣe o, OLUWA pe àwa ọba mẹtẹẹta jọ láti fi wá lé ọba Moabu lọ́wọ́.”

11 Ó bá bèèrè pé, “Ṣé kò sí wolii OLUWA kan níhìn-ín tí ó lè bá wa wádìí lọ́wọ́ OLUWA?”

Ọ̀kan ninu àwọn iranṣẹ Joramu bá dáhùn pé, “Eliṣa ọmọ Ṣafati, tí ó jẹ́ iranṣẹ Elija, wà níhìn-ín.”

12 Jehoṣafati dáhùn pé, “Wolii òtítọ́ ni.” Àwọn ọba mẹtẹẹta náà bá lọ sọ́dọ̀ rẹ̀.

13 Eliṣa sọ fún Joramu ọba pé, “Lọ sọ́dọ̀ àwọn wolii baba ati ìyá rẹ. Àbí, kí ló pa èmi ati ìwọ pọ̀?”

Joramu dáhùn pé, “Rárá, OLUWA ni ó ti pe àwa ọba mẹtẹẹta yìí jọ láti fi wá lé ọba Moabu lọ́wọ́.”

14 Eliṣa bá dáhùn pé, “Bí OLUWA àwọn ọmọ ogun, ẹni tí mò ń sìn ṣe wà láàyè, n kì bá tí dá ọ lóhùn bí kò bá sí ti Jehoṣafati, ọba Juda, tí ó bá ọ wá.”

15 Ó ní, “Ẹ pe akọrin kan wá.”

Bí akọrin náà ti ń kọrin ni agbára OLUWA bà lé Eliṣa,

16 ó bá ní, “OLUWA ní òun óo sọ àwọn odò gbígbẹ wọnyi di adágún omi.

17 Ẹ kò ní rí ìjì tabi òjò, sibẹsibẹ àwọn odò gbígbẹ náà yóo kún fún omi, ti yóo fi jẹ́ pé ẹ̀yin ati àwọn mààlúù yín ati àwọn ẹran ọ̀sìn yín yóo rí ọpọlọpọ omi mu.

18 Nǹkan kékeré ni èyí jẹ́ níwájú OLUWA, yóo fun yín ní agbára láti borí àwọn ará Moabu.

19 Ẹ óo ṣẹgun àwọn ìlú olódi ati àwọn ìlú dáradára wọn, ẹ óo gé gbogbo igi dáradára, ẹ ó dí gbogbo orísun omi wọn; ẹ óo sì da òkúta sí gbogbo ilẹ̀ oko wọn.”

20 Ní ọjọ́ keji, ní àkókò ìrúbọ òwúrọ̀, omi ya wá láti apá Edomu, títí tí gbogbo ilẹ̀ fi kún fún omi.

21 Nígbà tí àwọn ará Moabu gbọ́ pé àwọn ọba mẹtẹẹta ń bọ̀ láti gbógun tì wọ́n, wọ́n pe gbogbo àwọn tí wọ́n lè lọ sógun jọ, ati àgbà ati ọmọde, wọ́n sì fi wọ́n sí àwọn ààlà ilẹ̀ wọn.

22 Nígbà tí wọ́n jí ní òwúrọ̀ ọjọ́ keji, tí oòrùn ń ràn sórí omi náà, àwọn ará Moabu rí i pé omi tí ó wà níwájú àwọn pọ́n bí ẹ̀jẹ̀.

23 Wọ́n kígbe pé, “Ẹ wo ẹ̀jẹ̀! Dájúdájú àwọn ọba mẹtẹẹta wọnyi ti bá ara wọn jà, wọ́n sì ti pa ara wọn, ẹ jẹ́ kí á lọ kó ìkógun ninu ibùdó-ogun wọn.”

24 Ṣugbọn nígbà tí wọ́n dé ibùdó-ogun náà, àwọn ọmọ ogun Israẹli kọlù wọ́n, títí tí wọ́n fi sá pada; wọ́n sì ń pa wọ́n ní ìpakúpa bí wọ́n ti ń lé wọn lọ.

25 Wọ́n pa àwọn ìlú wọn run, gbogbo ilẹ̀ oko tí ó dára ni wọ́n da òkúta sí títí tí gbogbo wọn fi kún. Wọ́n dí gbogbo orísun omi, wọ́n sì gé gbogbo àwọn igi dáradára. Kiri Heresi tíí ṣe olú-ìlú wọn nìkan ni wọn kò pa run, ṣugbọn àwọn tí wọn ń ta kànnàkànnà yí i ká, wọ́n sì ṣẹgun rẹ̀.

26 Nígbà tí ọba Moabu rí i pé ogun náà le pupọ, ó mú ẹẹdẹgbẹrin (700) ọkunrin tí wọ́n ń lo idà, ó gbìyànjú láti la ààrin ogun kọjá níwájú ọba Edomu, ṣugbọn kò ṣeéṣe.

27 Nítorí náà, ó fi àkọ́bí rẹ̀ ọkunrin, tí ó yẹ kí ó jọba lẹ́yìn rẹ̀ rú ẹbọ sísun sí oriṣa Moabu, ní orí odi ìlú náà. Ibinu ńlá dé bá àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n sì fi í sílẹ̀, wọ́n pada lọ sí ilẹ̀ wọn.

Categories
ÀWỌN ỌBA KEJI

ÀWỌN ỌBA KEJI 4

Eliṣa Ran Opó Aláìní Kan Lọ́wọ́

1 Iyawo ọ̀kan ninu àwọn ọmọ àwọn wolii tọ Eliṣa lọ, ó sì sọ fún un pé, “Olúwa mi, iranṣẹ rẹ, ọkọ mi, ti kú, gẹ́gẹ́ bí o ti mọ̀, ó jẹ́ ẹni tí ó bẹ̀rù OLUWA nígbà ayé rẹ̀. Ẹnìkan tí ó jẹ lówó kí ó tó kú fẹ́ kó àwọn ọmọkunrin mi mejeeji lẹ́rú, nítorí gbèsè baba wọn.”

2 Eliṣa bèèrè pé, “Kí ni o fẹ́ kí n ṣe fún ọ? Sọ ohun tí o ní nílé fún mi.”

Obinrin náà dáhùn pé, “N kò ní ohunkohun, àfi ìkòkò òróró kan.”

3 Eliṣa sọ fún un pé, “Lọ yá ọpọlọpọ ìkòkò lọ́wọ́ àwọn aládùúgbò rẹ.

4 Lẹ́yìn náà, kí ìwọ ati àwọn ọmọ rẹ wọlé, nígbà tí ẹ bá sì ti ti ìlẹ̀kùn yín tán, ẹ bẹ̀rẹ̀ sí da òróró náà sinu àwọn ìkòkò náà, kí ẹ sì máa gbé wọn sí ẹ̀gbẹ́ kan bí wọ́n bá ti ń kún.”

5 Obinrin náà lọ sinu ilé rẹ̀ pẹlu àwọn ọmọ rẹ̀, wọ́n sì ti ìlẹ̀kùn wọn; ó bá bẹ̀rẹ̀ sí da òróró náà sinu àwọn ìkòkò náà bí àwọn ọmọ rẹ̀ ṣe ń gbé wọn wá.

6 Nígbà tí gbogbo àwọn ìkòkò náà kún, obinrin náà bèèrè bóyá ìkòkò kù, àwọn ọmọ rẹ̀ sì dáhùn pé ó ti tán, òróró náà sì dá.

7 Ó bá pada lọ sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún wolii Eliṣa. Eliṣa wí fún un pé, “Lọ ta àwọn òróró náà kí o sì san gbèsè rẹ ninu rẹ̀, kí ìwọ ati àwọn ọmọ rẹ máa ná ìyókù.”

Eliṣa ati Obinrin Ọlọ́rọ̀ Ará Ṣunemu

8 Ní ọjọ́ kan Eliṣa lọ sí Ṣunemu, níbi tí obinrin ọlọ́rọ̀ kan ń gbé; obinrin náà sì pe Eliṣa wọlé kí ó wá jẹun. Láti ìgbà náà, ilé obinrin yìí ni Eliṣa ti máa ń jẹun ní Ṣunemu.

9 Obinrin náà sọ fún ọkọ rẹ̀ pé, “Mo wòye pé ọkunrin tí ó ń wá síbí yìí jẹ́ ẹni mímọ́ Ọlọ́run.

10 Jẹ́ kí á ṣe yàrá kékeré kan sí òkè ilé wa, kí á gbé ibùsùn, tabili, àga ati fìtílà sibẹ, kí ó lè máa dé sibẹ nígbàkúùgbà tí ó bá wá síbí.”

11 Ní ọjọ́ kan tí Eliṣa pada lọ sí Ṣunemu, ó wọ inú yàrá náà lọ láti sinmi.

12 Ó bá rán Gehasi iranṣẹ rẹ̀ kí ó pe obinrin náà wá. Nígbà tí ó wọlé ó dúró níwájú Eliṣa.

13 Eliṣa sọ fún Gehasi kí ó bèèrè lọ́wọ́ obinrin náà ohun tí ó fẹ́ kí òun ṣe fún un, fún gbogbo nǹkan tí ó ti ṣe fún àwọn. Ó ní, bóyá ó fẹ́ kí òun sọ ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ fún ọba ni tabi fún balogun? Obinrin náà dáhùn pé ààrin àwọn eniyan òun ni òun ń gbé.

14 Eliṣa bá bèèrè lọ́wọ́ Gehasi pé, “Kí ni mo lè ṣe fún un nígbà náà?”

Gehasi ní, “Kò bímọ, ọkọ rẹ̀ sì ti di arúgbó.”

15 Eliṣa bá rán Gehasi kí ó pe obinrin náà wá. Nígbà tí ó dé, ó dúró ní ẹnu ọ̀nà.

16 Eliṣa sọ fún un pé, “Níwòyí àmọ́dún, o óo fi ọwọ́ rẹ gbé ọmọkunrin.”

Obinrin náà dáhùn pé, “Háà! Oluwa mi, eniyan Ọlọrun ni ọ́, nítorí náà má ṣe parọ́ fún iranṣẹbinrin rẹ.”

17 Ṣugbọn obinrin náà lóyún ó sì bí ọmọkunrin ní akoko náà ní ọdún tí ó tẹ̀lé e gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Eliṣa.

18 Ní ọjọ́ kan, lẹ́yìn tí ọmọ náà dàgbà, ó lọ bá baba rẹ̀ ninu oko níbi tí wọ́n ti ń kórè.

19 Lójijì, ó kígbe pe baba rẹ̀, ó ní, “Orí mi! Orí mi!”

Baba rẹ̀ sì sọ fún iranṣẹ kan kí ó gbé ọmọ náà lọ sọ́dọ̀ ìyá rẹ̀.

20 Nígbà tí iranṣẹ náà gbé ọmọ náà dé ọ̀dọ̀ ìyá rẹ̀, ìyá rẹ̀ gbé e lé ẹsẹ̀ títí ọmọ náà fi kú ní ọ̀sán ọjọ́ náà.

21 Obinrin náà bá gbé òkú ọmọ náà lọ sí yàrá Eliṣa, ó tẹ́ ẹ sí orí ibùsùn rẹ̀, ó ti ìlẹ̀kùn, ó sì jáde.

22 Ó kígbe pe ọkọ rẹ̀ pé, “Jọ̀wọ́ rán iranṣẹ kan sí mi pẹlu kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan. Mo fẹ́ sáré lọ rí eniyan Ọlọ́run, n óo pada dé kíákíá.”

23 Ọkọ rẹ̀ bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Kí ló dé tí o fi fẹ́ lọ rí i lónìí? Òní kì í ṣe ọjọ́ oṣù tuntun tabi ọjọ́ ìsinmi.”

Ó sì dáhùn pé, “Kò séwu.”

24 Lẹ́yìn tí wọ́n ti di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà ní gàárì tán, ó sọ fún iranṣẹ náà pé, “Jẹ́ kí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà máa sáré dáradára, kí ó má sì dẹ̀rìn, àfi bí mo bá sọ pé kí ó má sáré mọ́.”

25 Ó lọ bá Eliṣa ní orí òkè Kamẹli.

Eliṣa rí i tí ó ń bọ̀ lókèèrè, ó bá sọ fún Gehasi, iranṣẹ rẹ̀, pé, “Wò ó! Obinrin ará Ṣunemu nì ni ó ń bọ̀ yìí!

26 Sáré lọ pàdé rẹ̀ kí o sì bèèrè alaafia rẹ̀ ati ti ọkọ rẹ̀ ati ti ọmọ rẹ̀ pẹlu.”

Obinrin náà dá Gehasi lóhùn pé, “Alaafia ni gbogbo wa wà.”

27 Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ Eliṣa, ó wólẹ̀ níwájú rẹ̀, ó sì di ẹsẹ̀ rẹ̀ mú. Gehasi súnmọ́ ọn láti tì í kúrò, ṣugbọn Eliṣa wí fún un pé, “Fi obinrin náà sílẹ̀, ṣé o kò rí i pé inú rẹ̀ bàjẹ́ gidigidi ni? OLUWA kò sì bá mi sọ nǹkankan nípa rẹ̀.”

28 Obinrin náà bá sọ fún Eliṣa pé, “Ǹjẹ́ mo tọrọ ọmọ lọ́wọ́ rẹ bí? Ǹjẹ́ n kò sọ fún ọ kí o má ṣe tàn mí jẹ?”

29 Eliṣa bá sọ fún Gehasi pé, “Ṣe gírí, kí o mú ọ̀pá mi lọ́wọ́, kí o sì máa lọ. Bí o bá pàdé ẹnikẹ́ni lọ́nà, má ṣe kí i, bí ẹnikẹ́ni bá kí ọ, má dáhùn.”

30 Nígbà náà ni ìyá ọmọ náà wí pé “Bí OLUWA tí ń bẹ láàyè tí ẹ̀mí ìwọ pàápàá sì ń bẹ, n kò ní fi ọ́ sílẹ̀.” Gehasi bá dìde, ó bá a lọ.

31 Ó lọ fi ọ̀pá Eliṣa lé ọmọ náà lójú, ṣugbọn ọmọ náà kò jí. Ó bá pada lọ sọ fún Eliṣa pé ọmọ náà kò jí.

32 Nígbà tí Eliṣa dé ilé náà, ó bá òkú ọmọ náà lórí ibùsùn.

33 Ó wọlé síbi tí òkú ọmọ náà wà, ó ti ìlẹ̀kùn, ó sì gbadura sí OLUWA.

34 Ó nà gbalaja lé ọmọ náà lórí, ó fẹnu kò ó lẹ́nu, ó fojú kò ó lójú, ó sì gbé ọwọ́ lé ọwọ́ rẹ̀. Bí ó sì ti nà lé ọmọ náà, ara ọmọ náà bẹ̀rẹ̀ sí lọ́ wọ́ọ́rọ́.

35 Lẹ́yìn náà, ó dìde, ó rìn síwá sẹ́yìn ninu ilé náà, ó tún pada lọ nà lé ọmọ náà. Ọmọ náà sín lẹẹmeje, ó sì la ojú rẹ̀.

36 Lẹ́yìn náà, ó wí fún Gehasi pé kí ó pe obinrin ará Ṣunemu náà wá, Gehasi bá pè é. Nígbà tí obinrin náà dé, Eliṣa wí fún un pé kí ó gba ọmọ rẹ̀.

37 Obinrin náà wólẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì dojúbolẹ̀. Lẹ́yìn náà, ó mú ọmọ rẹ̀, ó sì jáde lọ.

Iṣẹ́ Ìyanu Meji Mìíràn

38 Eliṣa dé sí Giligali nígbà tí ìyàn wà ní ilẹ̀ náà. Bí àwọn ọmọ wolii ti jókòó níwájú rẹ̀, ó sọ fún àwọn iranṣẹ rẹ̀, ó ní, “Ẹ gbé ìkòkò ńlá léná kí ẹ sì se àsáró fún àwọn ọmọ wolii.”

39 Ọ̀kan ninu àwọn iranṣẹ náà lọ sí oko láti já ewébẹ̀, ó rí àjàrà tí ó máa ń hù ninu igbó, ó sì ká ninu èso rẹ̀. Nígbà tí ó dé ilé, ó rẹ́ wọn sinu ìkòkò àsáró náà láìmọ̀ ohun tí wọ́n jẹ́.

40 Wọ́n bu oúnjẹ fún àwọn ọmọ wolii láti jẹ. Bí wọ́n ti ń jẹ àsáró náà, wọ́n kígbe pé “Eniyan Ọlọrun, májèlé wà ninu ìkòkò yìí!” Wọn kò sì lè jẹ ẹ́ mọ́.

41 Eliṣa dáhùn, ó ní, “Ẹ bu oúnjẹ díẹ̀ wá.” Ó da oúnjẹ náà sinu ìkòkò, ó sì wí pé, “Bu oúnjẹ fún àwọn ọkunrin náà, kí wọ́n lè jẹun.” Kò sì sí oró májèlé ninu oúnjẹ náà mọ́.

42 Ọkunrin kan wá láti Baaliṣaliṣa, ó mú burẹdi àkọ́so èso wá fún eniyan Ọlọrun, ati ogún burẹdi tí a fi ọkà-baali ṣe ati ṣiiri ọkà tuntun ninu àpò rẹ̀. Eliṣa bá wí pé, “Ẹ kó wọn fún àwọn ọmọkunrin, kí wọ́n jẹ ẹ́.”

43 Ṣugbọn iranṣẹ rẹ̀ wí pé, “Báwo ni n óo ṣe wá gbé èyí kalẹ̀ níwájú ọgọrun-un eniyan láti jẹ?”

Eliṣa tún ní, “Kó wọn fún àwọn ọmọkunrin kí wọ́n jẹ ẹ́, nítorí pé OLUWA ní, ‘Wọn yóo jẹ, yóo sì ṣẹ́kù.’ ”

44 Iranṣẹ náà bá gbé oúnjẹ náà kalẹ̀ níwájú àwọn ọmọkunrin náà, wọ́n jẹ, ó sì ṣẹ́kù gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ OLUWA.

Categories
ÀWỌN ỌBA KEJI

ÀWỌN ỌBA KEJI 5

Naamani Gba Ìwòsàn

1 Naamani, olórí ogun Siria, jẹ́ eniyan pataki ati ọlọ́lá níwájú ọba Siria, nítorí pé nípasẹ̀ rẹ̀ ni OLUWA ṣe fún ilẹ̀ Siria ní ìṣẹ́gun. Ó jẹ́ akọni jagunjagun, ṣugbọn adẹ́tẹ̀ ni.

2 Iyawo Naamani ní iranṣẹbinrin kékeré kan tí àwọn ará Siria mú lẹ́rú wá láti ilẹ̀ Israẹli, nígbà tí wọ́n lọ bá wọn jagun.

3 Ní ọjọ́ kan, ọmọbinrin náà sọ fún ọ̀gá rẹ̀ pé, “Bí oluwa mi Naamani bá lọ sí ọ̀dọ̀ wolii tí ó wà ní Samaria, yóo rí ìwòsàn gbà.”

4 Nígbà tí Naamani gbọ́, ó sọ ohun tí ọmọbinrin náà sọ fún ọba.

5 Ọba Siria dáhùn pé, “Tètè lọ, n óo sì fi ìwé ranṣẹ sí ọba Israẹli.”

Naamani mú ìwọ̀n talẹnti fadaka mẹ́wàá ati ẹgbaata (6,000) ìwọ̀n ṣekeli wúrà ati ìpààrọ̀ aṣọ mẹ́wàá,

6 ó bá lọ sí ọ̀dọ̀ ọba Israẹli pẹlu ìwé náà. Ohun tí wọ́n kọ sinu ìwé náà nìyí, “Ẹni tí ó mú ìwé yìí wá ni Naamani, iranṣẹ mi, mo rán an wá sọ́dọ̀ rẹ kí o lè wò ó sàn ninu àrùn ẹ̀tẹ̀ rẹ̀.”

7 Nígbà tí ọba Israẹli ka ìwé náà ó fa aṣọ rẹ̀ ya láti fi ìbẹ̀rù rẹ̀ hàn, ó sì wí pé, “Èmi ha í ṣe Ọlọrun tí ó ní agbára ikú ati ìyè bí, tí ọba Siria fi rò wí pé mo lè wo eniyan sàn kúrò ninu ẹ̀tẹ̀? Èyí fi hàn pé ó ń wá ìjà ni.”

8 Nígbà tí Eliṣa gbọ́ pé ọba Israẹli ti fa aṣọ rẹ̀ ya, ó ranṣẹ sí i pé, “Kí ló dé tí o fi fa aṣọ rẹ ya? Mú ọkunrin náà wá sọ́dọ̀ mi, kí ó lè mọ̀ pé wolii kan wà ní Israẹli.”

9 Naamani bá lọ ti òun ti àwọn ẹṣin ati kẹ̀kẹ́-ogun rẹ̀, ó sì dúró lẹ́nu ọ̀nà ilé Eliṣa.

10 Eliṣa rán iranṣẹ kan kí ó sọ fún un pé kí ó lọ wẹ ara rẹ̀ ninu odò Jọdani ní ìgbà meje, yóo sì rí ìwòsàn.

11 Ṣugbọn Naamani fi ibinu kúrò níbẹ̀, ó ní, “Mo rò pé yóo jáde wá, yóo gbadura sí OLUWA Ọlọrun rẹ̀, yóo fi ọwọ́ rẹ̀ pa ibẹ̀, yóo sì ṣe àwòtán ẹ̀tẹ̀ náà ni.

12 Ṣé àwọn odò Abana ati odò Faripari tí wọ́n wà ní Damasku kò dára ju gbogbo àwọn odò tí wọ́n wà ní Israẹli lọ ni? Ṣebí mo lè wẹ̀ ninu wọn kí n sì mọ́!” Ó bá yipada, ó ń bínú lọ.

13 Àwọn iranṣẹ rẹ̀ bá gbà á níyànjú pé, “Baba, ṣé bí wolii náà bá sọ pé kí o ṣe ohun tí ó le ju èyí lọ, ṣé o kò ní ṣe é? Kí ló dé tí o kò lè wẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ti wí, kí o sì rí ìwòsàn gbà?”

14 Naamani bá lọ sí odò Jọdani, ó wẹ̀ ní ìgbà meje gẹ́gẹ́ bí Eliṣa ti pàṣẹ fún un, ó rí ìwòsàn, ara rẹ̀ sì jọ̀lọ̀ bí ara ọmọde.

15 Lẹ́yìn náà ó pada pẹlu àwọn iranṣẹ rẹ̀ sọ́dọ̀ Eliṣa, ó ní, “Nisinsinyii ni mo mọ̀ pé kò sí ọlọrun mìíràn ní gbogbo ayé àfi Ọlọrun Israẹli. Nítorí náà jọ̀wọ́ gba ẹ̀bùn yìí lọ́wọ́ iranṣẹ rẹ.”

16 Ṣugbọn Eliṣa dáhùn pé, “Mo fi OLUWA tí mò ń sìn búra pé n kò ní gba nǹkankan lọ́wọ́ rẹ.”

Naamani rọ̀ ọ́ kí ó gbà wọ́n, ṣugbọn ó kọ̀.

17 Naamani bá ní, “Jọ̀wọ́ fún mi ní ààyè láti bu erùpẹ̀ ẹrù kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ meji lọ sílé nítorí láti òní lọ, iranṣẹ rẹ kì yóo rúbọ sí ọlọrun mìíràn bíkòṣe OLUWA.

18 Mo bẹ̀bẹ̀ kí OLUWA dáríjì mí nígbà tí mo bá tẹ̀lé oluwa mi lọ sinu tẹmpili Rimoni, oriṣa Siria láti rúbọ sí i. Bí oluwa mi bá gbé ara lé apá mi, tí èmi náà sì tẹríba ninu tẹmpili Rimoni, kí OLUWA dáríjì iranṣẹ rẹ.”

19 Eliṣa sọ fún un pé “Máa lọ ní alaafia.” Naamani bá lọ.

Ṣugbọn kò tíì rìn jìnnà,

20 nígbà tí Gehasi, iranṣẹ Eliṣa, sọ ninu ara rẹ̀ pé, “Olúwa mi jẹ́ kí Naamani ará Siria yìí lọ láì gba ohun tí ó mú wá lọ́wọ́ rẹ̀. Mo fi OLUWA búra pé, n óo sáré tẹ̀lé e láti gba nǹkan lọ́wọ́ rẹ̀.”

21 Ó bá sáré tẹ̀lé Naamani. Nígbà tí Naamani rí i pé ẹnìkan ń sáré bọ̀, ó sọ̀kalẹ̀ lórí kẹ̀kẹ́ ogun tí ó gùn láti pàdé rẹ̀, ó bèèrè pé, “Ṣé kò sí nǹkan?”

22 Gehasi dáhùn pé, “Rárá, kò sí nǹkan. Oluwa mi ni ó rán mi sí ọ pé, ‘Nisinsinyii ni meji ninu àwọn ọmọ àwọn wolii tí wọn ń gbé òkè Efuraimu wá sọ́dọ̀ mi. Jọ̀wọ́ fún wọn ní ìwọ̀n talẹnti fadaka kan ati aṣọ meji.’ ”

23 Naamani sì rọ̀ ọ́ kí ó gba ìwọ̀n talẹnti meji. Ó di owó náà sinu àpò meji pẹlu aṣọ meji. Ó pàṣẹ fún iranṣẹ meji kí wọ́n bá Gehasi gbé wọn lọ.

24 Nígbà tí wọ́n dé orí òkè tí Eliṣa ń gbé, Gehasi gba àwọn ẹrù náà lórí wọn, ó gbé wọn sinu ilé, ó sì dá àwọn iranṣẹ Naamani pada.

25 Nígbà tí ó wọlé, Eliṣa bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Níbo ni o lọ?”

Ó dáhùn pé, “N kò lọ sí ibìkan kan.”

26 Eliṣa dáhùn pé, “Ṣé o kò mọ̀ pé mo wà pẹlu rẹ ninu ẹ̀mí, nígbà tí Naamani sọ̀kalẹ̀ ninu kẹ̀kẹ́-ogun, tí ó gùn, tí ó wá láti pàdé rẹ? Ṣé àkókò yìí ni ó yẹ láti gba fadaka tabi aṣọ tabi olifi tabi ọgbà àjàrà tabi aguntan tabi mààlúù tabi iranṣẹkunrin tabi iranṣẹbinrin?

27 Nítorí ìdí èyí, ẹ̀tẹ̀ Naamani yóo lẹ̀ mọ́ ọ lára ati ìdílé rẹ ati ìrandíran rẹ títí lae.”

Gehasi sì jáde kúrò lọ́dọ̀ Eliṣa ní adẹ́tẹ̀, ó funfun bíi ẹ̀gbọ̀n òwú.

Categories
ÀWỌN ỌBA KEJI

ÀWỌN ỌBA KEJI 6

Irin Àáké Léfòó

1 Ní ọjọ́ kan àwọn ọmọ àwọn wolii tí wọ́n wà lábẹ́ àkóso Eliṣa sọ fún un pé, “Ibi tí à ń gbé kéré jù fún wa.

2 Jọ̀wọ́ fún wa ní ààyè láti lọ gé igi ní etí odò Jọdani láti fi kọ́ ilé mìíràn tí a óo máa gbé.”

Eliṣa dáhùn pé, “Ó dára, ẹ máa lọ.”

3 Ọ̀kan ninu wọn bẹ̀ ẹ́ pé kí ó bá àwọn lọ, ó sì gbà bẹ́ẹ̀.

4 Gbogbo wọn jọ lọ, nígbà tí wọ́n dé etí odò Jọdani, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí gé igi.

5 Bí ọ̀kan ninu wọn ti ń gé igi, lójijì, irin àáké tí ó ń lò yọ bọ́ sinu odò. Ó kígbe pé, “Yéè! Oluwa mi, a yá àáké yìí ni!”

6 Eliṣa bèèrè pé, “Níbo ni ó bọ́ sí?”

Ọkunrin náà sì fi ibẹ̀ hàn án. Eliṣa gé igi kan, ó jù ú sinu omi, irin àáké náà sì léfòó lójú omi.

7 Eliṣa pàṣẹ fún un pé, “Mú un.” Ọkunrin náà bá mu irin àáké náà.

Israẹli Ṣẹgun Siria

8 Ní ìgbà kan tí ọba Siria ń bá ọba Israẹli jagun, ó bá àwọn olórí ogun rẹ̀ gbèrò ibi tí wọn yóo ba sí de àwọn ọmọ ogun Israẹli.

9 Eliṣa ranṣẹ sí ọba Israẹli pé kí ó má ṣe gba ibẹ̀ nítorí pé àwọn ará Siria ba sibẹ.

10 Ọba Israẹli bá ranṣẹ sí àwọn eniyan tí ń gbé ibi tí Eliṣa kilọ̀ fún un nípa rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ níí máa ń kìlọ̀ fún ọba Israẹli tí ọba Israẹli sì ń bọ́ kúrò ninu tàkúté ọba Siria. Ó ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀ ní ọpọlọpọ ìgbà.

11 Ọkàn ọba Siria kò balẹ̀ nítorí ọ̀rọ̀ yìí, nítorí náà, ó pe gbogbo àwọn olórí ogun rẹ̀ jọ, ó sì bi wọ́n pé, “Ta ló ń tú àṣírí wa fún ọba Israẹli ninu yín?”

12 Ọ̀kan ninu wọn dáhùn pé, “Kò sí ẹnìkan ninu wa tí ń sọ àṣírí fún ọba Israẹli. Wolii Eliṣa ní ń sọ fún un, títí kan gbogbo ohun tí ẹ bá sọ ní kọ̀rọ̀ yàrá yín.”

13 Ọba bá pàṣẹ pé, “Ẹ lọ wádìí ibi tí ó ń gbé, kí n lè ranṣẹ lọ mú un.”

Nígbà tí wọ́n sọ fún un pé Eliṣa wà ní Dotani,

14 ó rán ọpọlọpọ àwọn ọmọ ogun ati ẹṣin ati kẹ̀kẹ́-ogun lọ sibẹ. Ní òru ni wọ́n dé ìlú náà, wọ́n sì yí i po.

15 Ní òwúrọ̀ kutukutu, nígbà tí iranṣẹ Eliṣa jáde sí ìta, ó rí i pé àwọn ọmọ ogun Siria ti yí ìlú náà po pẹlu ẹṣin ati àwọn kẹ̀kẹ́-ogun. Ó pada wọlé tọ Eliṣa lọ, ó sì kígbe pé, “Yéè, oluwa mi, kí ni a óo ṣe?”

16 Eliṣa dáhùn pé, “Má bẹ̀rù nítorí pé àwọn tí wọ́n wà pẹlu wa ju àwọn tí wọ́n wà pẹlu wọn lọ.”

17 Eliṣa bá gbadura pé kí OLUWA jọ̀wọ́ ṣí ojú rẹ̀, kí ó lè ríran. OLUWA ṣí iranṣẹ náà lójú, ó sì rí i pé gbogbo orí òkè náà kún fún ẹṣin ati kẹ̀kẹ́ ogun, iná sí yí Eliṣa ká.

18 Nígbà tí àwọn ará Siria gbìyànjú láti mú un, ó gbadura pé kí OLUWA jọ̀wọ́ fọ́ àwọn ọkunrin náà lójú. OLUWA sì fọ́ wọn lójú gẹ́gẹ́ bí adura Eliṣa.

19 Eliṣa tọ̀ wọ́n lọ, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ ti ṣìnà; èyí kì í ṣe ìlú tí ẹ̀ ń wá, ẹ tẹ̀lé mi n óo fi ẹni tí ẹ̀ ń wá hàn yín.” Ó sì mú wọn lọ sí Samaria.

20 Ní kété tí wọ́n wọ Samaria, Eliṣa gbadura pé kí OLUWA ṣí wọn lójú kí wọ́n lè ríran. OLUWA sì ṣí wọn lójú, wọ́n rí i pé ààrin Samaria ni àwọn wà.

21 Nígbà tí ọba Israẹli rí wọn, ó bi Eliṣa pé, “Ṣé kí n pa wọ́n, oluwa mi, ṣé kí n pa wọ́n?”

22 Eliṣa dáhùn pé, “O kò gbọdọ̀ pa wọ́n, ṣé o máa pa àwọn tí o bá kó lójú ogun ni? Gbé oúnjẹ ati omi kalẹ̀ níwájú wọn, kí wọ́n jẹ, kí wọ́n mu, kí wọ́n sì pada sọ́dọ̀ oluwa wọn.”

23 Nítorí náà, ọba Israẹli pèsè oúnjẹ fún wọn lọpọlọpọ. Lẹ́yìn tí wọ́n ti jẹ, tí wọ́n sì ti mu, wọ́n pada sọ́dọ̀ oluwa wọn. Láti ọjọ́ náà ni àwọn ọmọ ogun Siria kò ti gbógun ti ilẹ̀ Israẹli mọ́.

Ogun Dóti Samaria

24 Lẹ́yìn èyí, Benhadadi, ọba Siria, kó gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jọ láti bá Israẹli jagun, wọ́n sì dóti ìlú Samaria.

25 Nítorí náà, ìyàn ńlá mú ní ìlú náà tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi ń ta orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ní ọgọrin ìwọ̀n ṣekeli fadaka ati idamẹrin òṣùnwọ̀n kabu ìgbẹ́ ẹyẹlé ní ìwọ̀n ṣekeli fadaka marun-un.

26 Bí ọba Israẹli ti ń rìn lórí odi ìlú, obinrin kan kígbe pè é, ó ní, “Olúwa mi, ọba, ràn mí lọ́wọ́.”

27 Ọba dáhùn pé, “Bí OLUWA kò bá ràn ọ́ lọ́wọ́, ìrànlọ́wọ́ wo ni èmi lè ṣe? Ṣé mo ní ìyẹ̀fun tabi ọtí waini ni?”

28 Ó bá bèèrè pé, “Kí ni ìṣòro rẹ?” Obinrin náà dáhùn, ó ní, “Obinrin yìí sọ fún mi pé kí n mú ọmọ mi wá kí á pa á jẹ, bí ó bá di ọjọ́ keji a óo pa ọmọ tirẹ̀ jẹ,

29 ni a bá pa ọmọ tèmi jẹ. Ní ọjọ́ keji, mo sọ fún un pé kí ó mú ọmọ tirẹ̀ wá kí á pa á jẹ, ṣugbọn ó fi ọmọ tirẹ̀ pamọ́.”

30 Nígbà tí ọba gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ó fa aṣọ rẹ̀ ya láti fi ìbànújẹ́ rẹ̀ hàn. Àwọn tí wọ́n wà lẹ́bàá odi níbi tí ó ń gbà lọ sì rí i pé ó wọ aṣọ-ọ̀fọ̀ sí abẹ́ aṣọ rẹ̀.

31 Ó sì búra pé kí OLUWA ṣe jù bẹ́ẹ̀ sí òun bí òun kò bá gé orí Eliṣa, ọmọ Ṣafati, kí ilẹ̀ ọjọ́ náà tó ṣú.

32 Eliṣa jókòó ninu ilé rẹ̀ pẹlu àwọn alàgbà. Ọba rán ọkunrin kan ṣáájú láti lọ pa á, ṣugbọn Eliṣa sọ fún àwọn alàgbà tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Wò ó, ọmọ apànìyàn yìí ti rán ẹnìkan láti wá pa mí, ọba fúnra rẹ̀ sì ń tẹ̀lé e bọ̀ lẹ́yìn. Bí iranṣẹ náà bá dé, ẹ ti ìlẹ̀kùn ẹnu ọ̀nà kí ó má lè wọlé.”

33 Bí ó ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́ ni ọba dé, ó ní, “Láti ọ̀dọ̀ OLUWA ni ibi yìí ti wá, kí ló dé tí n óo fi tún máa dúró de OLUWA fún ìrànlọ́wọ́?”

Categories
ÀWỌN ỌBA KEJI

ÀWỌN ỌBA KEJI 7

1 Eliṣa dáhùn pé, “Gbọ́ ọ̀rọ̀ OLUWA, ní àkókò yìí lọ́la, ní ẹnubodè Samaria, àwọn eniyan yóo ra òṣùnwọ̀n ìyẹ̀fun kíkúnná kan, tabi òṣùnwọ̀n ọkà baali meji ní ìwọ̀n ṣekeli kan.”

2 Ọ̀kan ninu àwọn ọ̀gágun tí wọ́n wà níbẹ̀, tí ó jẹ́ aṣojú ọba dá Eliṣa lóhùn, ó ní, “Bí OLUWA bá tilẹ̀ da àwọn nǹkan wọnyi sílẹ̀ láti ojú ọ̀run wá, ǹjẹ́ ohun tí o sọ yìí lè rí bẹ́ẹ̀?”

Eliṣa dá a lóhùn pé, “O óo fi ojú rí i, ṣugbọn o kò ní jẹ ninu rẹ̀.”

Ogun Siria pada Sílé

3 Àwọn adẹ́tẹ̀ mẹrin kan wà ní ẹnubodè Samaria, wọ́n sọ fún ara wọn pé, “Kí ló dé tí a óo fi dúró síbí títí tí a óo fi kú?

4 Bí a bá lọ sinu ìlú ebi yóo pa wá kú nítorí ìyàn wà níbẹ̀, bí a bá sì dúró níbí, a óo kú bákan náà. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á lọ sí ibùdó ogun àwọn ará Siria. Bí wọ́n bá pa wá, a jẹ́ pé ikú yá, bí wọ́n bá sì dá wa sí, a óo wà láàyè.”

5 Nígbà tí ọjọ́ bẹ̀rẹ̀ sí pofírí, wọ́n lọ sí ibùdó ogun àwọn ará Siria, nígbà tí wọ́n dé ibẹ̀, wọn kò rí ẹnìkan kan.

6 OLUWA ti mú kí àwọn ọmọ ogun Siria gbọ́ ìró ẹsẹ̀ kẹ̀kẹ́ ogun ati ẹṣin ati ọpọlọpọ àwọn ọmọ ogun. Wọ́n wí fún ara wọn pé ọba Israẹli ti lọ bẹ àwọn ọmọ ogun Hiti ati ti Ijipti láti wá bá àwọn jà.

7 Nítorí náà, wọ́n sá lọ ní àṣáálẹ́ ọjọ́ náà, wọ́n fi ibùdó ogun wọn ati àwọn ẹṣin wọn ati àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn sílẹ̀, wọ́n sì sá àsálà fún ẹ̀mí wọn.

8 Nígbà tí àwọn adẹ́tẹ̀ mẹrin náà dé ìkangun ibùdó ogun, wọ́n wọ inú àgọ́ kan lọ. Wọ́n jẹ ohun tí wọ́n bá níbẹ̀; wọ́n sì mu. Wọ́n kó fadaka ati wúrà ati aṣọ tí wọ́n rí níbẹ̀, wọ́n lọ kó wọn pamọ́. Wọ́n pada wá, wọ́n wọ inú àgọ́ mìíràn, wọ́n tún ṣe bákan náà.

9 Lẹ́yìn náà, wọ́n sọ fún ara wọn pé, “Ohun tí à ń ṣe yìí kò dára, ọjọ́ ìròyìn ayọ̀ ni ọjọ́ òní. Bí a bá dákẹ́, tí a sì dúró di òwúrọ̀ a óo jìyà. Ẹ jẹ́ kí á lọ sọ fún àwọn ará ilé ọba.”

10 Wọ́n bá lọ sí Samaria, wọ́n sì kígbe pe àwọn aṣọ́nà láti ẹnubodè pé, “A ti lọ sí ibùdó ogun àwọn ará Siria, a kò rí ẹnìkan kan níbẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni a kò gbúròó ẹnìkan kan. Àwọn ẹṣin ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn wà bí wọ́n ṣe so wọ́n mọ́lẹ̀, gbogbo àwọn àgọ́ wọn sì wà gẹ́gẹ́ bí àwọn ará Siria ti fi wọ́n sílẹ̀.”

11 Àwọn aṣọ́nà bá sọ fún àwọn tí wọ́n wà ní ààfin ọba.

12 Ọba dìde ní òru ọjọ́ náà, ó sọ fún àwọn olórí ogun rẹ̀ pé, “Mo mọ ète àwọn ará Siria. Wọ́n mọ̀ pé ìyàn mú ninu ìlú wa, nítorí náà ni wọ́n ṣe fi ibùdó ogun wọn sílẹ̀ láti sá pamọ́ sinu igbó, pẹlu èrò pé a óo wá oúnjẹ wá. Kí wọ́n lè mú wa láàyè, kí wọ́n sì gba ìlú wa.”

13 Ọ̀kan ninu àwọn olórí ogun náà dá ọba lóhùn pé, “Ṣebí àwọn eniyan náà yóo kú ni gẹ́gẹ́ bí àwọn tí wọ́n ti kú. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á rán àwọn ọkunrin kan pẹlu ẹṣin marun-un tí ó kù láti lọ wo ohun tí ó ṣẹlẹ̀.”

14 Ọba sì rán ọkunrin meji pẹlu kẹ̀kẹ́ ogun meji láti lọ wo ohun tí ó ṣẹlẹ̀.

15 Àwọn ọkunrin náà lọ títí dé odò Jọdani. Ní gbogbo ojú ọ̀nà náà ni wọ́n ti ń rí àwọn aṣọ ati àwọn ohun ìjà tí àwọn ará Siria jù sọnù nígbà tí wọn ń sá lọ. Wọ́n sì pada wá ròyìn fún ọba.

16 Àwọn ará Samaria sì tú jáde láti lọ kó ìkógun ní ibùdó ogun àwọn ará Siria. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí OLUWA ti sọ, wọ́n ta òṣùnwọ̀n ìyẹ̀fun kíkúnná kan ní ìwọ̀n ṣekeli kan.

17 Ọba Israẹli fi ìtọ́jú ẹnubodè ìlú sí abẹ́ àkóso ọ̀gágun tí ó jẹ́ aṣojú rẹ̀. Àwọn eniyan sì tẹ ọ̀gágun náà pa, gẹ́gẹ́ bí Eliṣa ti sọtẹ́lẹ̀ nígbà tí ọba lọ sọ́dọ̀ rẹ̀.

18 Nítorí nígbà tí eniyan Ọlọrun sọ fún ọba pé, “Ní ìwòyí ọ̀la, lẹ́nu bodè Samaria, àwọn eniyan yóo máa ra òṣùnwọ̀n ìyẹ̀fun kíkúnná kan tabi òṣùnwọ̀n ọkà baali meji ní ìwọ̀n ṣekeli kọ̀ọ̀kan,”

19 ọ̀gágun náà dáhùn pé, “Ǹjẹ́ èyí lè ṣẹ, bí OLUWA tilẹ̀ rọ̀jò àwọn nǹkan wọnyi sílẹ̀ láti ojú ọ̀run wá.” Eliṣa sì dá a lóhùn pé, “O óo fi ojú rẹ rí i, ṣugbọn o kò ní jẹ ninu rẹ̀.”

20 Ó sì rí bẹ́ẹ̀ fún un, nítorí àwọn eniyan tẹ ọ̀gágun náà pa ní ẹnubodè ìlú.

Categories
ÀWỌN ỌBA KEJI

ÀWỌN ỌBA KEJI 8

Obinrin Ará Ṣunemu náà Pada

1 Eliṣa sọ fún obinrin ará Ṣunemu, ẹni tí Eliṣa jí ọmọ rẹ̀ tí ó kú pé, “OLUWA yóo rán ìyàn sí ilẹ̀ yìí fún ọdún meje, nítorí náà, kí ìwọ ati ẹbí rẹ lọ máa gbé ní ilẹ̀ mìíràn.”

2 Obinrin náà gbọ́ ọ̀rọ̀ Eliṣa, òun ati ẹbí rẹ̀ sì lọ ń gbé ilẹ̀ àwọn ará Filistia fún ọdún meje.

3 Lẹ́yìn ọdún keje, obinrin náà pada sí Israẹli, ó sì lọ sọ́dọ̀ ọba láti bẹ̀ ẹ́ pé kí ó dá ilé ati ilẹ̀ òun pada.

4 Ó bá ọba tí ó ń bá Gehasi iranṣẹ Eliṣa sọ̀rọ̀; ọba fẹ́ mọ̀ nípa àwọn iṣẹ́ ìyanu Eliṣa.

5 Bí Gehasi ti ń sọ fún ọba bí Eliṣa ṣe jí òkú dìde, ni obinrin tí Eliṣa jí òkú ọmọ rẹ̀ dìde wá sọ ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ fún ọba. Gehasi sọ fún ọba pé, “Olúwa mi, obinrin náà nìyí, ọmọkunrin rẹ̀ tí Eliṣa jí dìde náà sì nìyí.”

6 Ọba bèèrè lọ́wọ́ obinrin náà, ó sì sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún ọba. Ọba bá pàṣẹ fún ọ̀kan ninu àwọn iranṣẹ rẹ̀ kí ó fún obinrin náà ní gbogbo ohun tíí ṣe tirẹ̀ pẹlu gbogbo ohun tí wọ́n ti kórè ninu oko náà, láti ìgbà tí obinrin náà ti fi ìlú sílẹ̀ títí di ìgbà tí ó pada dé.

Eliṣa ati Benhadadi Ọba Siria

7 Eliṣa lọ sí Damasku ní àkókò kan tí Benhadadi ọba Siria wà lórí àìsàn. Nígbà tí wọ́n sọ fún ọba pé Eliṣa wà ní Damasku,

8 ọba sọ fún Hasaeli, ọ̀kan ninu àwọn iranṣẹ rẹ̀ pé, “Mú ẹ̀bùn lọ́wọ́, kí o sì lọ bá wolii náà, kí o sọ fún un pé kí ó bá mi bèèrè lọ́wọ́ OLUWA bóyá n óo yè ninu àìsàn yìí.”

9 Hasaeli di ogoji ẹrù ràkúnmí tí ó kún fún oniruuru ohun rere tí ó wà ní Damasku, ó lọ bá Eliṣa. Nígbà tí Hasaeli pàdé rẹ̀, ó sọ pé, “Iranṣẹ rẹ, Benhadadi, ọba Siria, rán mi láti bèèrè lọ́wọ́ rẹ bóyá òun óo yè ninu àìsàn òun.”

10 Eliṣa dáhùn pé, “OLUWA ti fi hàn mí pé yóo kú, ṣugbọn lọ sọ fún un pé yóo yè.”

11 Eliṣa tẹjú mọ́ Hasaeli títí ojú fi tì í. Eliṣa sì sọkún.

12 Hasaeli bèèrè pé, “Kí ló dé tí o fi ń sunkún, oluwa mi?”

Eliṣa dáhùn pé, “Nítorí pé mo mọ oríṣìíríṣìí nǹkan burúkú tí o óo ṣe sí àwọn ọmọ Israẹli: O óo jó ibi ààbò wọn, o óo fi idà pa àwọn ọmọkunrin wọn, o óo tú àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ wọn ká, o óo sì la inú àwọn aboyún wọn.”

13 Hasaeli dáhùn pé, “Ta ni mí, tí n óo fi ṣe nǹkan tí ó lágbára tóbẹ́ẹ̀?”

Eliṣa dáhùn pé, “OLUWA ti fi hàn mí pé o óo jọba ní Siria.”

14 Ó bá pada lọ sọ́dọ̀ Benhadadi, ó sì bèèrè ohun tí Eliṣa sọ lọ́wọ́ rẹ̀.

Hasaeli dáhùn pé, “O óo yè ninu àìsàn rẹ.”

15 Ní ọjọ́ keji Hasaeli mú aṣọ tí ó nípọn, ó rì í bọ omi, ó sì fi bo ojú Benhadadi títí ó fi kú.

Hasaeli sì jọba lẹ́yìn rẹ̀.

Jehoramu Ọba Juda

16 Ní ọdún karun-un tí Joramu ọmọ Ahabu jọba ní Israẹli, ni Jehoramu ọmọ Jehoṣafati jọba ní ilẹ̀ Juda.

17 Ẹni ọdún mejilelọgbọn ni, nígbà tí ó jọba, ó sì jọba fún ọdún mẹjọ.

18 Ó tẹ̀ sí ọ̀nà àwọn ọba Israẹli gẹ́gẹ́ bí ilé Ahabu nítorí ọmọ Ahabu, ni iyawo rẹ̀, ó ṣe ibi níwájú OLUWA.

19 Sibẹsibẹ OLUWA kò pa Juda run nítorí ó ti búra fún Dafidi iranṣẹ rẹ̀ pé ìran rẹ̀ yóo máa jọba ní ilẹ̀ Juda.

20 Ní àkókò ìjọba Jehoramu, Edomu ṣọ̀tẹ̀ sí Juda, wọ́n sì yan ọba fún ara wọn.

21 Nítorí náà, Jehoramu kó gbogbo àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, wọ́n lọ sí Sairi láti bá Edomu jagun. Níbẹ̀ ni àwọn ọmọ ogun Edomu ti yí wọn ká. Ní òru, òun ati àwọn olórí ogun rẹ̀ kọlu àwọn ará Edomu tí wọ́n yí wọn ká, wọ́n sì sá àsálà, ṣugbọn àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sá pada sí ilé wọn.

22 Láti ìgbà náà ni Edomu ti di òmìnira kúrò lọ́wọ́ Juda. Ní àkókò kan náà ni ìlú Libina ṣọ̀tẹ̀ sí Juda.

23 Gbogbo àwọn nǹkan yòókù tí Jehoramu ṣe ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Juda.

24 Jehoramu kú, wọ́n sì sin ín sí ibojì àwọn ọba ní ìlú Dafidi. Ahasaya ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀.

Ahasaya Ọba Juda

25 Ní ọdún kejila tí Joramu ọmọ Ahabu ti jọba ní Israẹli ni Ahasaya, ọmọ Jehoramu, jọba ní ilẹ̀ Juda.

26 Ẹni ọdún mejilelogun ni nígbà tí ó jọba ni Jerusalẹmu, ó sì jọba fún ọdún kan. Atalaya ni ìyá rẹ̀, ọmọ Omiri, ọba ilẹ̀ Israẹli.

27 Ọ̀nà ìdílé Ahabu ọba ni Ahasaya tẹ̀ sí, ó sì ṣe burúkú níwájú OLUWA, bí ìdílé Ahabu ti ṣe; nítorí pé àna ló jẹ́ fún Ahabu.

28 Ahasaya bá Joramu, ọba Israẹli lọ, wọ́n gbógun ti Hasaeli, ọba Siria, ní Ramoti Gileadi. Àwọn ọmọ ogun Siria ṣá ọba Joramu lọ́gbẹ́.

29 Ó pada sí ìlú Jesireeli, ó lọ wo ọgbẹ́ náà sàn. Ahasaya, ọba Juda, ọmọ Jehoramu, sì lọ bẹ̀ ẹ́ wò ní Jesireeli.

Categories
ÀWỌN ỌBA KEJI

ÀWỌN ỌBA KEJI 9

A fi Òróró Yan Jehu ní Ọba Israẹli

1 Eliṣa pe ọ̀kan ninu àwọn ọmọ àwọn wolii, ó sọ fún un pé, “Ṣe kánkán, kí o lọ sí Ramoti Gileadi pẹlu ìgò òróró yìí.

2 Nígbà tí o bá dé ibẹ̀, bèèrè Jehu, ọmọ Jehoṣafati, ọmọ Nimṣi; mú un wọ yàrá kan lọ kúrò láàrin àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀.

3 Kí o da òróró inú ìgò yìí sí i lórí, kí o sì wí pé, OLUWA sọ pé, ‘Mo fi òróró yàn ọ́ ní ọba lórí Israẹli.’ Kí o sì yára sá kúrò níbẹ̀.”

4 Ọdọmọkunrin wolii náà bá lọ sí Ramoti Gileadi.

5 Nígbà tí ó dé ibẹ̀, ó bá àwọn olórí ogun níbi tí wọ́n ti ń ṣe ìpàdé. Ó wí pé, “Balogun, wọ́n rán mi níṣẹ́ sí ọ.”

Jehu bá bèèrè pé, “Ta ni ninu wa?”

Ọdọmọkunrin náà bá dáhùn pé, “Ìwọ ni, Balogun.”

6 Àwọn mejeeji bá jọ wọ inú yàrá lọ, ọdọmọkunrin wolii náà da òróró sí orí Jehu, ó sì wí pé, “Báyìí ni OLUWA Ọlọrun Israẹli wí, ‘Mo fi òróró yàn ọ́ ní ọba lórí Israẹli, àwọn eniyan OLUWA.’

7 O óo pa ìdílé oluwa rẹ, Ahabu ọba rẹ́, kí n lè gbẹ̀san lára Jesebẹli fún àwọn wolii mi ati àwọn iranṣẹ mi tí ó pa.

8 Gbogbo ìdílé Ahabu ni yóo ṣègbé, n óo sì pa gbogbo àwọn ọmọkunrin tí wọ́n wà ninu ìdílé náà, ati ẹrú ati ọmọ.

9 N óo ṣe ìdílé Ahabu bí mo ti ṣe àwọn ìdílé Jeroboamu ọmọ Nebati, ati ìdílé Baaṣa ọba, ọmọ Ahija.

10 Ajá ni yóo jẹ òkú Jesebẹli ní agbègbè Jesireeli, kò sí ẹni tí yóo sin òkú rẹ̀.” Lẹ́yìn tí ó ti sọ̀rọ̀ náà tán, ó ṣí ìlẹ̀kùn, ó sá lọ.

11 Nígbà tí Jehu pada sí ọ̀dọ̀ àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀, wọ́n bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Ṣé kò sí nǹkan? Kí ni ọkunrin bíi wèrè yìí ń wá lọ́dọ̀ rẹ?”

Jehu dáhùn pé, “Ǹjẹ́ ẹ mọ ọkunrin náà, ati ohun tí ó sọ?”

12 Wọ́n dáhùn pé, “Rárá, a kò mọ̀ ọ́n, sọ fún wa.”

Jehu sì dáhùn pé, “Ó sọ fún mi pé OLUWA ti fi òróró yàn mí ní ọba lórí Israẹli.”

13 Lẹ́sẹ̀ kan náà, àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ tẹ́ aṣọ wọn sílẹ̀ fún un kí ó dúró lé, wọ́n sì fun fèrè pé, “Kabiyesi, Jehu ọba!”

Wọ́n pa Joramu, Ọba Israẹli

14 Jehu, ọmọ Jehoṣafati, ọmọ Nimṣi, dìtẹ̀ mọ́ Joramu. (Ní àkókò yìí Joramu ati àwọn ọmọ ogun Israẹli ń ṣọ́ Hasaeli ọba Siria ní Ramoti Gileadi;

15 ṣugbọn Joramu ọba ti lọ sí Jesireeli láti tọ́jú ọgbẹ́ tí wọ́n ṣá a lójú ogun Siria.) Jehu sọ fún àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ pé, “Bí ẹ bá wà lẹ́yìn mi, ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni jáde kúrò ní ìlú láti lọ ròyìn fún wọn ní Jesireeli.”

16 Jehu gun kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, ó lọ sí Jesireeli nítorí ibẹ̀ ni Joramu ọba wà, Ahasaya, ọba Juda sì wá bẹ̀ ẹ́ wò níbẹ̀.

17 Ọ̀kan ninu àwọn aṣọ́nà tí ó wà ninu ilé ìṣọ́ ní Jesireeli rí i tí Jehu ati àwọn ọkunrin rẹ̀ ń bọ̀. Ó sì kígbe pé, “Mo rí àwọn ọkunrin kan tí wọ́n ń gun kẹ̀kẹ́ ogun bọ̀.”

Joramu dáhùn pé, “Rán ẹlẹ́ṣin kan láti bèèrè bóyá alaafia ni.”

18 Ẹlẹ́ṣin kan lọ pàdé rẹ̀, ó ní, “Ọba wí pé, ṣé alaafia ni?”

Jehu dá a lóhùn pé, “Kí ni o ní ṣe pẹlu alaafia? Bọ́ sẹ́yìn mi.” Olùṣọ́ náà wí pé, “Oníṣẹ́ náà dé ọ̀dọ̀ wọn ṣugbọn kò pada wá.”

19 Wọ́n bá tún rán oníṣẹ́ mìíràn lọ láti bèèrè ìbéèrè kan náà lọ́wọ́ Jehu. Ó tún dáhùn pé “Kí ni o fẹ́ fi alaafia ṣe? Bọ́ sẹ́yìn mi.”

20 Olùṣọ́ bá tún jíṣẹ́ fun ọba pé, “Oníṣẹ́ náà dé ọ̀dọ̀ wọn, ṣugbọn kò pada.” Ó tún fi kún un pé, “Wọ́n ń wa kẹ̀kẹ́ ogun wọn bíi Jehu, ọmọ Nimṣi, nítorí wọ́n ń wà á pẹlu ibinu.”

21 Joramu ọba pàṣẹ pé kí wọ́n gbé kẹ̀kẹ́ ogun òun wá, wọ́n sì gbé e wá fún un. Joramu ọba ati Ahasaya, ọba Juda sì jáde lọ pàdé Jehu, olukuluku ninu kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀. Wọ́n pàdé rẹ̀ ninu oko Naboti ara Jesireeli.

22 Joramu bèèrè pé, “Ṣé alaafia ni?”

Jehu dáhùn pé, “Alaafia ṣe lè wà níwọ̀n ìgbà tí ìwà àgbèrè ati àjẹ́ ìyá rẹ ṣì wà sibẹ.”

23 Joramu bá kígbe pé, “Ọ̀tẹ̀ nìyí, Ahasaya!” Ó yí kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ pada, ó ń sá lọ.

24 Jehu fi gbogbo agbára ta ọfà rẹ̀, ó bá Joramu lẹ́yìn, ó wọ inú ọkàn rẹ̀ lọ, Joramu sì kú sinu kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀.

25 Jehu sọ fún Bidikari, ẹni tí ń ru ihamọra rẹ̀, ó ní, “Gbé òkú rẹ̀ kí o jù ú sinu oko Naboti. Ṣé o ranti pé, nígbà tí èmi pẹlu rẹ ń gun kẹ̀kẹ́ ogun lẹ́yìn Ahabu baba rẹ̀, OLUWA sọ ọ̀rọ̀ wọnyi nípa Ahabu,

26 pé, ‘Mo rí i bí o ti pa Naboti ati àwọn ọmọ rẹ̀ lánàá, dájúdájú n óo jẹ ọ́ níyà ninu oko kan náà.’ Nítorí náà gbé òkú rẹ̀ jù sinu oko Naboti gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ OLUWA.”

A Pa Ahasaya Ọba Juda

27 Nígbà tí Ahasaya rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀, ó sá gba ọ̀nà Beti Hagani lọ. Jehu bẹ̀rẹ̀ sí lépa rẹ̀, ó pàṣẹ fún àwọn ọkunrin rẹ̀ pé kí wọ́n ta á lọ́fà! Wọ́n sì ta á lọ́fà ninu kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ ní ọ̀nà Guri lẹ́bàá Ibileamu, ó sá lọ sí Megido, níbẹ̀ ni ó sì kú sí.

28 Àwọn olórí ogun rẹ̀ gbé òkú rẹ̀ sinu kẹ̀kẹ́ ogun kan lọ sí Jerusalẹmu. Wọ́n sin ín sinu ibojì àwọn baba rẹ̀ ní ìlú Dafidi.

29 Ahasaya jọba ní ilẹ̀ Juda ní ọdún kọkanla tí Joramu ọmọ Ahabu ti jọba ní Israẹli.

A pa Jesebẹli Ayaba

30 Nígbà tí Jehu dé Jesireeli, Jesebẹli gbọ́; ó lé tìróò, ó di irun rẹ̀, ó sì ń yọjú wo ìta láti ojú fèrèsé ní òkè.

31 Bí Jehu ti gba ẹnu ọ̀nà wọlé, Jesebẹli kígbe pé, “Ṣé alaafia ni, Simiri? Ìwọ tí o pa oluwa rẹ!”

32 Jehu bá gbé ojú rẹ̀ sókè, ó ní, “Ta ló wà lẹ́yìn mi ninu yín?” Àwọn ìwẹ̀fà meji tabi mẹta sì yọjú sí i láti ojú fèrèsé.

33 Jehu bá ké sí wọn, ó ni, “Ẹ Jù ú sílẹ̀.” Wọ́n bá ju Jesebẹli sí ìsàlẹ̀, ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sì ta sí ara ògiri ati sí ara àwọn ẹṣin, àwọn ẹṣin Jehu sì tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀ kọjá.

34 Lẹ́yìn náà, ó wọlé, ó jẹ, ó mu, lẹ́yìn náà, ó ní, “Ẹ lọ sin òkú obinrin ẹni ègún yìí nítorí pé ọmọ ọba ni.”

35 Àwọn ọkunrin tí wọ́n lọ sin òkú náà kò rí nǹkankan àfi agbárí, ati egungun ọwọ́ ati ti ẹsẹ̀ rẹ̀.

36 Nígbà tí wọ́n pada wá sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún Jehu, ó ní, “OLUWA ti sọ tẹ́lẹ̀ láti ẹnu wolii Elija, iranṣẹ rẹ̀ pé, ajá ni yóo jẹ òkú Jesebẹli ní agbègbè Jesireeli.

37 Òkú rẹ̀ yóo fọ́n ká bí ìgbẹ́ tóbẹ́ẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò ní lè dá a mọ̀ mọ́.”