Categories
ÀWỌN ADÁJỌ́

ÀWỌN ADÁJỌ́ 20

Israẹli Múra Ogun

1 Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli jáde wá, bẹ̀rẹ̀ láti Dani ní apá ìhà àríwá títí dé Beeriṣeba ní apá ìhà gúsù ilẹ̀ Israẹli ati àwọn tí wọ́n wà ní ilẹ̀ Gileadi, ní apá ìwọ̀ oòrùn. Wọ́n kó ara wọn jọ sójú kan ṣoṣo níwájú OLUWA ní Misipa.

2 Gbogbo àwọn olórí láàrin àwọn eniyan náà jákèjádò ilẹ̀ Israẹli kó ara wọn jọ pẹlu ìjọ eniyan Ọlọ́run. Àwọn ọmọ ogun tí wọn ń fi ẹsẹ̀ rìn, tí wọ́n sì ń lo idà, tí wọ́n kó ara wọn jọ níbẹ̀ tàwọn ti idà lọ́wọ́ wọn jẹ́ ogún ọ̀kẹ́ (400,000).

3 Àwọn ẹ̀yà Bẹnjamini gbọ́ pé àwọn ọmọ Israẹli ti kó ara wọn jọ ní Misipa.

Àwọn ọmọ Israẹli bèèrè lọ́wọ́ ọmọ Lefi náà pé, “Sọ fún wa, báwo ni nǹkan burúkú yìí ti ṣe ṣẹlẹ̀?”

4 Ọmọ Lefi, ọkọ obinrin tí wọ́n pa, bá dáhùn pé, “Èmi ati obinrin mi ni a yà sí Gibea ní ilẹ̀ àwọn ará Bẹnjamini pé kí á sùn níbẹ̀.

5 Àwọn ọkunrin Gibea bá dìde lóru, wọ́n yí ilé tí mo wà po, wọ́n fẹ́ pa mí. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bá obinrin mi lòpọ̀ títí tí ó fi kú.

6 Mo bá gbé òkú rẹ̀, mo gé e lékìrí lékìrí, mo bá fi ranṣẹ sí gbogbo ilẹ̀ Israẹli jákèjádò, nítorí pé àwọn eniyan wọnyi ti ṣe nǹkan burúkú ati ohun ìríra ní Israẹli.

7 Gbogbo ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ gba ọ̀rọ̀ yí yẹ̀wò, kí ẹ sì mú ìmọ̀ràn yín wá lórí rẹ̀ nisinsinyii.”

8 Gbogbo àwọn eniyan náà bá fi ohùn ṣọ̀kan pé, “Ẹnikẹ́ni ninu wa kò ní pada sí àgọ́ rẹ̀ tabi ilé rẹ̀.

9 Ohun tí a óo ṣe nìyí, gègé ni a óo ṣẹ́ láti mọ àwọn tí yóo gbógun ti Gibea.

10 Ìdámẹ́wàá àwọn ọkunrin tí wọ́n wà ní Israẹli yóo máa pèsè oúnjẹ fún àwọn ọmọ ogun, àwọn yòókù yóo lọ jẹ àwọn ará Gibea níyà fún ìwà burúkú tí wọ́n hù ní Israẹli yìí.”

11 Gbogbo àwọn ọkunrin Israẹli bá kó ara wọn jọ, wọ́n gbógun ti ìlú náà.

12 Àwọn ọmọ Israẹli rán oníṣẹ́ jákèjádò ilẹ̀ Bẹnjamini, wọ́n ní, “Irú ìwà ìkà wo ni ẹ hù yìí?

13 Nítorí náà, ẹ kó àwọn aláìníláárí eniyan tí wọn ń hu ìwà ìkà ní Gibea jáde fún wa, kí á sì pa wọ́n, kí á mú ibi kúrò láàrin Israẹli.” Ṣugbọn àwọn ọmọ Bẹnjamini kò gba ohun tí àwọn arakunrin wọn, àwọn ọmọ Israẹli ń wí.

14 Àwọn ọmọ Bẹnjamini bá kó ara wọn jọ láti gbogbo ìlú ńláńlá, wọ́n wá sí Gibea láti gbógun ti àwọn ọmọ Israẹli.

15 Àwọn ọmọ ogun tí àwọn ará Bẹnjamini kó jọ ní ọjọ́ náà jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ati ẹgbaata (26,000) àwọn ọkunrin tí wọn ń lo idà; láì ka àwọn tí wọn ń gbé Gibea tí àwọn náà kó ẹẹdẹgbẹrin (700) akọni ọkunrin jọ.

16 Ẹẹdẹgbẹrin (700) akọni ọkunrin tí wọn ń lo ọwọ́ òsì wà láàrin àwọn ọmọ ogun wọnyi. Wọ́n mọ kànnàkànnà ta, tóbẹ́ẹ̀ tí ó jẹ́ pé wọ́n lè ta á mọ́ fọ́nrán òwú láì tàsé.

17 Láì ka àwọn tí àwọn ará Bẹnjamini náà kó jọ, àwọn ọmọ Israẹli kó ogún ọ̀kẹ́ (400,000) jagunjagun tí wọn ń lo idà jọ.

Israẹli Bá Ẹ̀yà Bẹnjamini Jagun

18 Àwọn ọmọ Israẹli gbéra lọ sí Bẹtẹli, wọ́n lọ wádìí lọ́dọ̀ Ọlọrun; ẹ̀yà tí yóo kọ́kọ́ gbógun ti ẹ̀yà Bẹnjamini.

OLUWA dá wọn lóhùn pé ẹ̀yà Juda ni yóo kọ́kọ́ gbógun tì wọ́n.

19 Àwọn ọmọ Israẹli bá gbéra ní òwúrọ̀ ọjọ́ keji, wọ́n lọ pàgọ́ sí òdìkejì Gibea,

20 wọ́n bá gbógun ti àwọn ẹ̀yà Bẹnjamini, wọ́n fi ìlú Gibea ṣe ojú ogun wọn.

21 Àwọn ará Bẹnjamini bá jáde sí wọn láti ìlú Gibea, wọ́n sì pa ọ̀kẹ́ kan (20,000) ninu àwọn ọmọ ogun Israẹli ní ọjọ́ náà.

22 Ṣugbọn àwọn ọmọ Israẹli mọ́kàn le, wọ́n tún gbógun tì wọ́n, wọ́n sì tún fi ibi tí wọ́n fi ṣe ojú ogun tẹ́lẹ̀ ṣe ojú ogun wọn.

23 Wọ́n bá lọ sọkún níwájú OLUWA títí di ìrọ̀lẹ́, wọ́n wádìí lọ́dọ̀ OLUWA, wọ́n ní, “Ṣé kí á tún gbógun ti àwọn ará Bẹnjamini tí í ṣe àwọn arakunrin wa?”

OLUWA dá wọn lóhùn pé kí wọ́n lọ gbógun tì wọ́n.

24 Àwọn ọmọ Israẹli bá tún lọ gbógun ti àwọn ọmọ ogun Bẹnjamini ní ọjọ́ keji.

25 Àwọn ará Bẹnjamini bá tún jáde láti Gibea ní ọjọ́ keji, wọ́n pa ọ̀kẹ́ kan ó dín ẹgbaa (18,000) eniyan ninu àwọn ọmọ Israẹli, gbogbo wọn jẹ́ jagunjagun tí ń fi idà jà.

26 Gbogbo àwọn ọmọ ogun Israẹli bá lọ sí Bẹtẹli, wọ́n jókòó wọ́n sọkún níbẹ̀ níwájú OLUWA, wọ́n gbààwẹ̀ títí di ìrọ̀lẹ́; wọ́n sì rú ẹbọ sísun ati ẹbọ alaafia níwájú OLUWA.

27 Àwọn ọmọ Israẹli tún wádìí lọ́dọ̀ OLUWA, nítorí pé àpótí majẹmu Ọlọrun wà ní Bẹtẹli ní àkókò náà.

28 Finehasi ọmọ Eleasari, ọmọ Aaroni ló ń ṣe iṣẹ́ alufaa ní àkókò náà, àwọn ọmọ Israẹli tún bèèrè pé, “Ṣé kí á tún lọ gbógun ti àwọn ará Bẹnjamini tíí ṣe arakunrin wa àbí kí á dáwọ́ dúró?”

OLUWA dá wọn lóhùn, ó ní, “Ẹ lọ gbógun tì wọ́n, nítorí pé, lọ́la ni n óo fi wọ́n le yín lọ́wọ́.”

29 Àwọn ọmọ Israẹli bá fi àwọn eniyan pamọ́ ní ibùba, yípo gbogbo Gibea.

30 Àwọn ọmọ Israẹli tún gbógun ti àwọn ọmọ Bẹnjamini ní ọjọ́ kẹta, wọ́n tò yípo Gibea bíi ti iṣaaju.

31 Àwọn ará Bẹnjamini jáde sí wọn, àwọn ọmọ Israẹli bẹ̀rẹ̀ sí fi ọgbọ́n tàn wọ́n kúrò ní ìlú; àwọn ará Bẹnjamini tún bẹ̀rẹ̀ sí pa ninu àwọn ọmọ Israẹli bíi ti iṣaaju. Wọ́n pa wọ́n ní ojú òpópó ọ̀nà tí ó lọ sí Bẹtẹli ati Gibea ati ninu pápá. Àwọn tí wọ́n pa ninu wọ́n tó ọgbọ̀n eniyan.

32 Àwọn ará Bẹnjamini wí fún ara wọn pé, “A tún ti tú wọn ká bíi ti iṣaaju.”

Ṣugbọn àwọn ọmọ Israẹli wí pé, “Ẹ jẹ́ kí á sá, kí á sì tàn wọ́n kúrò ninu ìlú wọn, kí wọ́n bọ́ sí ojú òpópó.”

33 Olukuluku àwọn ọmọ Israẹli bá kúrò ní ààyè rẹ̀, wọ́n lọ tò ní Baalitamari. Àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n ba ní ibùba bá jáde kúrò níbi tí wọ́n ba sí ní apá ìwọ̀ oòrùn Geba.

34 Ni ẹgbaarun (10,000) àṣàyàn àwọn jagunjagun ninu àwọn ọmọ Israẹli bá gbógun ti ìlú Gibea. Ogun náà gbóná gidigidi ṣugbọn àwọn ará Bẹnjamini kò mọ̀ pé ewu ńlá súnmọ́ tòsí wọn.

35 OLUWA bá ṣẹgun àwọn ará Bẹnjamini fún àwọn ọmọ Israẹli. Àwọn ọmọ Israẹli pa ọ̀kẹ́ kan ati ẹgbẹẹdọgbọn ó lé ọgọrun-un (25,100) eniyan ninu àwọn ará Bẹnjamini lọ́jọ́ náà. Gbogbo àwọn tí wọ́n pa jẹ́ jagunjagun tí wọn ń lo idà.

Ìṣẹ́gun Israẹli

36 Àwọn ọmọ Bẹnjamini rí i pé wọ́n ti ṣẹgun àwọn. Nígbà tí, àwọn ọmọ Israẹli ṣebí ẹni ń sá lọ fún àwọn ara Bẹnjamini, wọ́n ń tàn wọ́n jáde ni, wọ́n sì ti gbẹ́kẹ̀lé àwọn ará wọn tí wọ́n ba ní ibùba yípo Gibea láti gbógun ti àwọn ará Bẹnjamini.

37 Àwọn tí wọ́n ba ní ibùba yára jáde, wọ́n gbógun ti Gibea, wọ́n sì fi idà pa gbogbo àwọn ará ìlú náà run.

38 Àmì tí àwọn ọmọ Israẹli ati àwọn tí wọ́n ba ní ibùba ti jọ ṣe fún ara wọn ni pé, nígbà tí wọ́n bá rí i tí èéfín ńlá yọ sókè ní Gibea,

39 kí àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n ti ń sá lọ yipada, kí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí jagun. Àwọn ará Bẹnjamini ti pa bí ọgbọ̀n jagunjagun ninu àwọn Israẹli, wọ́n sì ti ń wí ninu ará wọn pé, “Dájúdájú a ti ṣẹgun wọn bíi ti àkọ́kọ́.”

40 Ṣugbọn nígbà tí èéfín tí àwọn ọmọ ogun Israẹli fi ṣe àmì bẹ̀rẹ̀ sí yọ sókè láàrin ìlú, àwọn ará Bẹnjamini wo ẹ̀yìn, wọ́n rí i pé èéfín ti sọ, ó sì ti gba ìlú kan.

41 Àwọn ọmọ Israẹli bá yipada sí wọn, ìdààmú sì bá àwọn ọmọ Bẹnjamini nítorí wọ́n rí i pé ewu ńlá súnmọ́ tòsí.

42 Nítorí náà, wọ́n pada lẹ́yìn àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ sí ìhà aṣálẹ̀, ṣugbọn ọwọ́ bà wọ́n, nítorí pé ààrin àwọn jagunjagun tí wọ́n yipada sí wọn, ati àwọn tí wọn ń jáde bọ̀ láti inú ìlú ni wọ́n bọ́ sí.

43 Àwọn ọmọ Israẹli bẹ̀rẹ̀ sí pa wọ́n láì dáwọ́ dúró bí wọn ti ń lé wọn lọ. Wọ́n pa wọ́n láti Nohahi títí dé iwájú ìlà oòrùn Gibea.

44 Ọ̀kẹ́ kan ó dín ẹgbaa (18,000) ninu àwọn akikanju ará Bẹnjamini ni àwọn ọmọ Israẹli pa.

45 Wọ́n bá yipada, wọ́n sá gba ọ̀nà aṣálẹ̀ tí ó lọ sí ibi àpáta Rimoni, àwọn ọmọ Israẹli sì tún pa ẹẹdẹgbaata (5,000) ninu wọn ní ojú ọ̀nà. Wọ́n ń lé wọn lọ tete títí dé Gidomu, wọ́n sì tún pa ẹgbaa (2,000) eniyan ninu wọn.

46 Gbogbo àwọn tí wọ́n kú ninu àwọn ọmọ Bẹnjamini ní ọjọ́ náà jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹẹdẹgbaata (25,000); gbogbo wọ́n jẹ́ akikanju jagunjagun tí ń lo idà.

47 Ṣugbọn ẹgbẹta (600) ọkunrin ninu wọn sá lọ sí apá aṣálẹ̀, síbi àpáta Rimoni, wọ́n sì ń gbé inú àpáta Rimoni náà fún oṣù mẹrin.

48 Àwọn ọmọ Israẹli bá yipada sí àwọn ará Bẹnjamini, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí pa gbogbo àwọn tí wọ́n bá fojú kàn, ati eniyan ati ẹranko. Gbogbo ìlú wọn tí wọ́n rí ni wọ́n sì sun níná.

Categories
ÀWỌN ADÁJỌ́

ÀWỌN ADÁJỌ́ 21

Àwọn Ẹ̀yà Bẹnjamini Fẹ́ Iyawo

1 Àwọn ọmọ Israẹli ti búra nígbà tí wọ́n wà ní Misipa pé, “Ẹnikẹ́ni ninu wa kò ní fi ọmọ rẹ̀ fún ará Bẹnjamini.”

2 Àwọn eniyan bá wá sí Bẹtẹli, wọ́n jókòó níwájú Ọlọrun títí di ìrọ̀lẹ́, wọ́n sì sọkún gidigidi.

3 Wọ́n wí pé, “OLUWA Ọlọrun Israẹli, kí ló dé tí irú èyí fi ṣẹlẹ̀ ní Israẹli, tí ó fi jẹ́ pé lónìí ẹ̀yà Israẹli dín kan?”

4 Nígbà tí ó di ọjọ́ keji, àwọn eniyan náà dìde ní òwúrọ̀ kutukutu, wọ́n tẹ́ pẹpẹ kan, wọ́n sì rú ẹbọ sísun ati ẹbọ alaafia níbẹ̀.

5 Àwọn ọmọ Israẹli bèèrè pé, “Èwo ninu gbogbo ẹ̀yà Israẹli ni kò wá sí ibi àjọ níwájú OLUWA?” Nítorí pé wọ́n ti ṣe ìbúra tí ó lágbára nípa ẹni tí kò bá wá siwaju OLUWA ní Misipa, wọ́n ní, “Pípa ni a óo pa á.”

6 Àwọn ọmọ Israẹli bẹ̀rẹ̀ sí káàánú àwọn ẹ̀yà Bẹnjamini arakunrin wọn, wọ́n ní, “Ẹ̀yà Israẹli dín kan lónìí.

7 Báwo ni a óo ṣe rí aya fún àwọn tí ó ṣẹ́kù; nítorí pé a ti fi OLUWA búra pé a kò ní fi àwọn ọmọbinrin wa fún wọn?”

8 Wọ́n bá bèèrè pé, “Ẹ̀yà wo ninu Israẹli ni kò wá siwaju OLUWA ní Misipa?” Wọ́n rí i pé ẹnikẹ́ni kò wá ninu àwọn ará Jabeṣi Gileadi sí àjọ náà.

9 Nítorí pé nígbà tí àwọn eniyan náà kó ara wọn jọ, ẹnikẹ́ni láti inú àwọn tí ń gbé ìlú Jabeṣi Gileadi kò sí níbẹ̀.

10 Ìjọ eniyan náà bá rán ẹgbaafa (12,000) ninu àwọn jagunjagun wọn tí wọ́n gbójú jùlọ, wọ́n sì fún wọn láṣẹ pé, “Ẹ lọ fi idà pa gbogbo àwọn tí ń gbé Jabeṣi Gileadi ati obinrin wọn, ati àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ wọn.

11 Ohun tí ẹ ó ṣe nìyí: gbogbo ọkunrin wọn ati gbogbo obinrin tí ó bá ti mọ ọkunrin, pípa ni kí ẹ pa wọ́n.”

12 Wọ́n rí irinwo (400) ọdọmọbinrin tí kò tíì mọ ọkunrin lára àwọn tí wọn ń gbé ìlú Jabeṣi Gileadi, wọ́n sì kó wọn wá sí àgọ́ ní Ṣilo, tí ó wà ní ilẹ̀ Kenaani.

13 Ni ìjọ eniyan bá ranṣẹ sí àwọn ará Bẹnjamini tí wọ́n wà níbi àpáta Rimoni, pé ìjà ti parí, alaafia sì ti dé.

14 Nígbà náà ni àwọn ará Bẹnjamini tó pada wá, àwọn ọmọ Israẹli sì fún wọn ní àwọn obinrin tí wọ́n mú láàyè ninu àwọn obinrin Jabeṣi Gileadi, ṣugbọn àwọn obinrin náà kò kárí wọn.

15 Àánú àwọn ọmọ Bẹnjamini bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àwọn ọmọ Israẹli nítorí pé OLUWA ti dín ọ̀kan kù ninu ẹ̀yà Israẹli.

16 Àwọn àgbààgbà ìjọ eniyan náà bá bèèrè pé, “Níbo ni a óo ti rí aya fún àwọn tí wọ́n ṣẹ́kù, níwọ̀n ìgbà tí a ti pa àwọn obinrin ẹ̀yà Bẹnjamini run.”

17 Wọ́n bá dáhùn pé, “Àwọn tí wọ́n kù ninu àwọn ara Bẹnjamini gbọdọ̀ ní ogún tiwọn, kí odidi ẹ̀yà kan má baà parun patapata ní Israẹli.

18 Ṣugbọn sibẹsibẹ, a kò gbọdọ̀ fi àwọn ọmọ wa fún wọn.” Nítorí pé àwọn ọmọ Israẹli ti búra pé, “Ẹni ègún ni ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ọmọ fún ará Bẹnjamini.”

19 Wọ́n bá pinnu pé, “Ọdọọdún ni a máa ń ṣe àjọ̀dún OLUWA ní Ṣilo, tí ó wà ní apá àríwá Bẹtẹli, ní apá ìlà oòrùn òpópó ọ̀nà tí ó lọ láti Bẹtẹli sí Ṣekemu, ní apá gúsù Lebona.”

20 Wọ́n bá fún àwọn ọkunrin Bẹnjamini láṣẹ pé, “Ẹ lọ ba ní ibùba ninu ọgbà àjàrà,

21 kí ẹ máa ṣọ́ àwọn ọmọbinrin Ṣilo bí wọ́n bá wá jó; ẹ jáde láti inú ọgbà àjàrà, kí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín ki iyawo kọ̀ọ̀kan mọ́lẹ̀ ninu àwọn ọmọbinrin Ṣilo, kí ẹ sì gbé wọn sá lọ sí ilẹ̀ Bẹnjamini.

22 Nígbà tí àwọn baba wọn, tabi àwọn arakunrin wọn bá wá fi ẹjọ́ sùn wá, a óo dá wọn lóhùn pé, ‘Ẹ fi wọ́n sílẹ̀ fún wọn nítorí pé àwọn obinrin tí a rí fún wọn ninu ogún kò kárí; kì í kúkú ṣe pé ẹ fi àwọn ọmọbinrin wọnyi fún wọn ni, tí ègún yóo fi ṣẹ le yín lórí.’ ”

23 Àwọn ará Bẹnjamini bá ṣe bí wọ́n ti sọ fún wọn. Olukuluku wọn gbé obinrin kọ̀ọ̀kan sá lọ ninu àwọn tí wọ́n wá jó, gbogbo wọn sì pada lọ sí ilẹ̀ wọn, wọ́n tún ìlú wọn kọ́, wọ́n sì ń gbé ibẹ̀.

24 Àwọn ọmọ Israẹli bá kúrò níbẹ̀, gbogbo wọ́n sì pada sí ilẹ̀ wọn, olukuluku pada lọ sí ìlú rẹ̀, sí ààrin ẹbí rẹ̀.

25 Kò sí ọba ní ilẹ̀ Israẹli ní gbogbo àkókò náà, olukuluku bá bẹ̀rẹ̀ sí ṣe bí ó ti tọ́ ní ojú ara rẹ̀.