Categories
AISAYA

AISAYA 60

Ògo Ọjọ́ Iwájú Jerusalẹmu

1 Dìde, tan ìmọ́lẹ̀; nítorí ìmọ́lẹ̀ rẹ ti dé,

ògo OLUWA sì ti tàn sára rẹ.

2 Nítorí òkùnkùn yóo bo ayé mọ́lẹ̀,

òkùnkùn biribiri yóo sì bo àwọn orílẹ̀-èdè mọ́lẹ̀,

ṣugbọn ìmọ́lẹ̀ OLUWA yóo tàn sára rẹ,

ògo OLUWA yóo sì hàn lára rẹ.

3 Àwọn orílẹ̀-èdè yóo wá sinu ìmọ́lẹ̀ rẹ,

àwọn ọba yóo sì wá sinu ìmọ́lẹ̀ rẹ tí ń tàn.

4 Gbé ojú sókè kí o wò yíká,

gbogbo wọn kó ara wọn jọ, wọ́n wá sí ọ̀dọ̀ rẹ;

àwọn ọmọ rẹ ọkunrin yóo wá láti òkèèrè,

a óo sì gbé àwọn ọmọ rẹ obinrin lé apá wá.

5 Nígbà tí o bá rí wọn,

inú rẹ yóo dùn,

ara rẹ óo yá gágá.

Ọkàn rẹ yóo kún fún ayọ̀,

nítorí pé a óo gbé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ọrọ̀ inú òkun wá sọ́dọ̀ rẹ.

Àwọn orílẹ̀-èdè yóo kó ọrọ̀ wọn wá fún ọ.

6 Ogunlọ́gọ̀ ràkúnmí yóo yí ọ ká,

àwọn ọmọ ràkúnmí Midiani ati Efa.

Gbogbo àwọn tí wọn wà ní Ṣeba yóo wá,

wọn óo mú wúrà ati turari wá;

wọn óo sì máa pòkìkí OLUWA.

7 Gbogbo ẹran ọ̀sìn Kedari ni wọ́n óo kó wá fún ọ,

wọn óo kó àgbò Nebaiotu wá ta ọ́ lọ́rẹ.

Wọn óo jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà lórí pẹpẹ mi,

ilé mi lógo, ṣugbọn n óo tún ṣe é lógo sí i.

8 Ta ni àwọn wọnyi tí ń fò lọ bí ìkùukùu?

Bí ìgbà tí àwọn àdàbà bá ń fò lọ sí ibi ìtẹ́ wọn?

9 Nítorí àwọn erékùṣù yóo dúró dè mí,

ọkọ̀ ojú omi Taṣiṣi ni yóo ṣiwaju

wọn óo kó àwọn ọmọkunrin rẹ wá láti ilẹ̀ òkèèrè,

wọn óo kó wúrà ati fadaka wá pẹlu wọn;

nítorí orúkọ OLUWA Ọlọrun rẹ,

ati Ẹni Mímọ́ Israẹli,

nítorí ó ti ṣe ọ́ lógo.

10 OLUWA ní, “Àwọn àjèjì ni yóo máa tún odi rẹ mọ,

àwọn ọba wọn yóo sì máa ṣe iranṣẹ fún ọ;

nítorí pé inú ló bí mi ni mo fi nà ọ́.

Ṣugbọn nítorí ojurere mi ni mo fi ṣàánú fún ọ.

11 Ṣíṣí ni ìlẹ̀kùn rẹ yóo máa wà nígbà gbogbo,

a kò ní tì wọ́n tọ̀sán-tòru;

kí àwọn eniyan lè máa kó ọrọ̀ orílẹ̀-èdè wá fún ọ,

pẹlu àwọn ọba wọn tí wọn yóo máa tì siwaju.

12 Orílẹ̀-èdè tabi ilẹ̀ ọba tí kò bá sìn ọ́ yóo parun,

wọn óo di àwópalẹ̀ patapata.

13 “Ògo Lẹbanoni yóo wá sí ọ̀dọ̀ rẹ:

igi sipirẹsi, igi firi, ati igi pine;

láti bukun ẹwà ilé mímọ́ mi,

n óo sì ṣe ibi ìtìsẹ̀ mi lógo.

14 Àwọn ọmọ àwọn tí ń ni ọ́ lára yóo wá,

wọn óo tẹríba fún ọ;

gbogbo àwọn tí ń kẹ́gàn rẹ,

yóo wá tẹríba lẹ́bàá ẹsẹ̀ rẹ;

wọn óo pè ọ́ ní ìlú OLÚWA,

Sioni ti Ẹni Mímọ́ Israẹli.

15 “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti kọ̀ ọ́,

wọ́n sì kórìíra rẹ,

tí kò sí ẹni tí ń gba ààrin rẹ̀ kọjá mọ́,

n óo sọ ọ́ di àmúyangàn títí lae;

àní, ohun ayọ̀ láti ìrandíran.

16 O óo mu wàrà àwọn orílẹ̀-èdè,

o óo mu wàrà àwọn ọba.

O óo sì mọ̀ pé èmi OLUWA, ni olùgbàlà rẹ,

ati Olùràpadà rẹ, Ẹni Ńlá Jakọbu.

17 “Dípò bàbà, wúrà ni n óo mú wá.

Dípò irin, fadaka ni n óo mú wá.

Dípò igi, bàbà ni n óo mú wá.

Dípò òkúta, irin ni n óo mú wá.

N óo mú kí àwọn alabojuto yín wà ní alaafia,

àwọn akóniṣiṣẹ́ yín yóo sì máa ṣe òdodo.

18 Kò tún ní sí ìró ìdàrúdàpọ̀ ní ilẹ̀ rẹ mọ́,

kò sì ní sí ìdágìrì ati ìparun ní ibodè rẹ,

o óo máa pe odi rẹ ní ìgbàlà,

o óo sì máa pe ẹnubodè rẹ ní ìyìn.

19 “Kì í ṣe oòrùn ni yóo máa tan ìmọ́lẹ̀ fún ọ mọ́ ní ọ̀sán,

bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe òṣùpá ni yóo máa tan ìmọ́lẹ̀ fún ọ mọ́ ní òru:

OLUWA ni yóo máa jẹ́ ìmọ́lẹ̀ ayérayé fún ọ,

Ọlọrun rẹ yóo sì jẹ́ ògo rẹ.

20 Oòrùn rẹ kò ní wọ̀ mọ́,

bẹ́ẹ̀ ni òṣùpá rẹ kò ní wọ òkùnkùn.

Nítorí OLUWA ni yóo jẹ́ ìmọ́lẹ̀ ayérayé fún ọ,

ọjọ́ ọ̀fọ̀ rẹ yóo sì dópin.

21 Gbogbo àwọn eniyan rẹ yóo jẹ́ olódodo,

àwọn ni yóo jogún ilẹ̀ náà títí lae.

Àwọn ni ẹ̀ka igi tí mo gbìn, iṣẹ́ ọwọ́ mi,

kí á baà lè yìn mí lógo.

22 Ìdílé tí ó rẹ̀yìn jùlọ yóo di orílẹ̀-èdè,

èyí tí ó sì kéré jùlọ yóo di orílẹ̀-èdè ńlá,

Èmi ni OLUWA,

kíákíá ni n óo ṣe é nígbà tí àkókò rẹ̀ bá tó.”

Categories
AISAYA

AISAYA 61

Ìròyìn Ayọ̀ Ìdáǹdè

1 Ẹ̀mí OLUWA, Ọlọrun tí bà lé mi,

nítorí ó ti fi àmì òróró yàn mí,

láti mú ìròyìn ayọ̀ wá fún àwọn tí a ni lára.

Ó rán mi pé kí n máa tu àwọn tí ó ní ìbànújẹ́ ninu,

kí n máa kéde ìdásílẹ̀ fún àwọn tí ó wà ní ìgbèkùn,

kí n sì máa ṣí ìlẹ̀kùn ọgbà ẹ̀wọ̀n sílẹ̀ fún àwọn ẹlẹ́wọ̀n.

2 Ó ní kí n máa kéde ọdún ojurere OLUWA,

ati ọjọ́ ẹ̀san Ọlọrun wa;

kí n sì máa tu àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ ninu.

3 Ó ní kí n máa fún àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ ní Sioni,

ní inú dídùn dípò ìkáàánú,

kí n fún wọn ní ayọ̀ dípò ìbànújẹ́,

kí n jẹ́ kí wọn máa kọrin ìyìn dípò ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn,

kí á lè máa pè wọ́n ní igi òdodo,

tí OLUWA gbìn,

kí á lè máa yìn ín lógo.

4 Wọn óo tún àlàpà ahoro àtijọ́ kọ́,

wọn óo tún gbogbo ilé tí ó ti wó lulẹ̀ kọ́,

wọn óo sì tún ìlú tí a ti parun láti ọdún gbọọrọ kọ́.

5 Àwọn àjèjì ni yóo máa ba yín bọ́ agbo ẹran yín,

àwọn ni yóo sì máa ṣe alágbàṣe ninu ọgbà àjàrà yín;

6 ṣugbọn a óo máa pe ẹ̀yin ní alufaa OLUWA,

àwọn eniyan yóo sì máa sọ̀rọ̀ yín bí iranṣẹ Ọlọrun wa.

Ẹ̀yin ni ẹ óo máa jẹ ọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn,

ọrọ̀ wọn ni ẹ óo sì máa fi ṣògo.

7 Dípò ìtìjú ìpín tiyín yóo jẹ́ meji,

dípò àbùkù ẹ óo láyọ̀ ninu ìpín tí ó kàn yín.

Ìlọ́po meji ni ìpín yín yóo jẹ́ ninu ilẹ̀ yín,

ayọ̀ ayérayé yóo sì jẹ́ tiyín.

8 OLUWA ní,

“Nítorí pé mo fẹ́ ẹ̀tọ́,

mo sì kórìíra ìfipá jalè ati ohun tí kò tọ́.

Dájúdájú n óo san ẹ̀san fún wọn,

n óo sì bá wọn dá majẹmu ayérayé.

9 Àwọn ọmọ wọn yóo dá yàtọ̀ láàrin orílẹ̀-èdè,

a óo dá arọmọdọmọ wọn mọ̀ láàrin àwọn eniyan,

gbogbo àwọn tí ó bá rí wọn,

yóo gbà pé èmi OLUWA ti bukun wọn.”

10 N óo máa yọ̀ ninu OLUWA,

ọkàn mi yóo kún fún ayọ̀ sí Ọlọrun mi.

Nítorí ó ti fi ìgbàlà wọ̀ mí bí ẹ̀wù,

ó sì ti fi òdodo bòmí lára bí aṣọ;

bí ọkọ iyawo tí ó ṣe ara rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́,

ati bí iyawo tí ó ṣe ọ̀ṣọ́ jìngbìnnì.

11 Bí ilẹ̀ tíí mú kí ewéko hù jáde,

tí ọgbà sì ń mú kí ohun tí a gbìn sinu rẹ̀ hù,

bẹ́ẹ̀ ni OLUWA Ọlọrun yóo mú kí òdodo ati orin ìyìn yọ jáde

níwájú gbogbo orílẹ̀-èdè.

Categories
AISAYA

AISAYA 62

1 Nítorí Sioni, ń kò ní dákẹ́,

nítorí Jerusalẹmu, ń kò ní sinmi,

títí ìdáláre rẹ̀ yóo fi yọ bí ìmọ́lẹ̀,

tí ìgbàlà rẹ̀ yóo sì tàn bí àtùpà.

2 Àwọn orílẹ̀-èdè yóo rí ìdáláre rẹ,

gbogbo ọba ni yóo rí ògo rẹ;

orúkọ tuntun, tí OLUWA fúnra rẹ̀ yóo sọ ọ́,

ni a óo máa pè ọ́.

3 O óo jẹ́ adé ẹwà lọ́wọ́ OLUWA,

ati fìlà oyè lọ́wọ́ Ọlọrun rẹ.

4 A kò ní pè ọ́ ní “Ẹni-tí-a-kọ̀-sílẹ̀” mọ́,

bẹ́ẹ̀ ni a kò ní pe ilẹ̀ rẹ ní “Ahoro” mọ́,

“Ẹni-OLUWA-fẹ́” ni a óo máa pè ọ́,

a óo máa pe ilẹ̀ rẹ ní “Ẹni-a-gbé-níyàwó.”

Nítorí pé OLUWA nífẹ̀ẹ́ rẹ,

ilẹ̀ rẹ yóo sì dàbí iyawo lójú rẹ̀.

5 Bí ọdọmọkunrin tií nífẹ̀ẹ́ wundia,

bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọkunrin rẹ yóo nífẹ̀ẹ́ rẹ.

Bí inú ọkọ iyawo tuntun tíí dùn nítorí iyawo rẹ̀,

bẹ́ẹ̀ ni inú Ọlọrun rẹ yóo dùn nítorí rẹ.

6 Jerusalẹmu, mo ti fi àwọn aṣọ́de sí orí odi rẹ;

lojoojumọ, tọ̀sán-tòru, wọn kò gbọdọ̀ panumọ́.

Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń rán OLUWA létí,

ẹ má dákẹ́.

7 Ẹ má jẹ́ kí ó sinmi,

títí yóo fi fi ìdí Jerusalẹmu múlẹ̀,

títí yóo fi sọ ọ́ di ìlú ìyìn láàrin gbogbo ayé.

8 OLUWA ti fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ búra,

ó ti fi agbára rẹ̀ jẹ́ ẹ̀jẹ́,

pé òun kò ní fi ọkà oko rẹ,

ṣe oúnjẹ fún àwọn ọ̀tá rẹ mọ́;

àwọn àjèjì kò sì ní mu ọtí waini rẹ,

tí o ṣe wahala lé lórí mọ́.

9 Ṣugbọn àwọn tí ó bá gbin ọkà, ni yóo máa jẹ ẹ́,

wọn óo sì máa fìyìn fún OLUWA;

àwọn tí ó bá sì kórè àjàrà ni yóo mu ọtí rẹ̀,

ninu àgbàlá ilé mímọ́ mi.

10 Ẹ kọjá! Ẹ gba ẹnubodè kọjá,

ẹ tún ọ̀nà ṣe fún àwọn eniyan.

Ẹ la ọ̀nà, ẹ la òpópónà,

kí ẹ ṣa òkúta kúrò níbẹ̀.

Ẹ ta àsíá sókè, fún àwọn eniyan náà.

11 Wò ó! OLUWA ti kéde títí dé òpin ayé.

Ó ní, “Ẹ sọ fún àwọn ará Jerusalẹmu pé,

‘Wò ó, olùgbàlà yín ti dé,

èrè rẹ wà pẹlu rẹ̀,

ẹ̀san rẹ sì wà níwájú rẹ̀.’ ”

12 A óo máa pè yín ní, “Eniyan mímọ́”,

“Ẹni-Ìràpadà-OLUWA”.

Wọn óo máa pè yín ní,

“Àwọn-tí-a-wá-ní-àwárí”;

wọn óo sì máa pe Jerusalẹmu ní,

“Ìlú tí a kò patì”.

Categories
AISAYA

AISAYA 63

Ìṣẹ́gun OLUWA lórí Àwọn Orílẹ̀-Èdè

1 “Ta ni ń ti Edomu bọ̀ yìí,

tí ó wọ aṣọ àlàárì, tí ń bọ̀ láti Bosira,

tí ó yọ bí ọjọ́ ninu aṣọ tí ó wọ̀,

tí ń yan bọ̀ ninu agbára ńlá rẹ̀.”

“Èmi ni, èmi tí mò ń kéde ẹ̀san,

tí mo sì lágbára láti gbani là.”

2 “Kí ló dé tí aṣọ rẹ fi pupa,

tí ó dàbí ti ẹni tí ń fún ọtí waini?”

3 OLUWA dáhùn, ó ní, “Èmi nìkan ni mo tí ń fún ọtí waini,

ẹnikẹ́ni kò bá mi fún un ninu àwọn eniyan mi.

Mo fi ibinu tẹ̀ wọ́n bí èso àjàrà,

mo fi ìrúnú tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀.

Ẹ̀jẹ̀ wọn bá dà sí mi láṣọ:

ó ti di àbààwọ́n sára gbogbo aṣọ mi.

4 Nítorí ọjọ́ ẹ̀san ló wà lọ́kàn mi,

ọdún ìràpadà mi sì ti dé.

5 Mo wò yíká, ṣugbọn kò sí olùrànlọ́wọ́,

ẹnu yà mí pé, n kò rí ẹnìkan tí yóo gbé mi ró;

nítorí náà, agbára mi ni mo fi ṣẹgun,

ibinu mi ni ó sì gbé mi ró.

6 Mo fi ibinu tẹ àwọn orílẹ̀-èdè mọ́lẹ̀,

mo fi ìrúnú rọ wọ́n yó,

mo sì tú ẹ̀jẹ̀ wọn dà sílẹ̀.”

Oore OLUWA sí Israẹli

7 N óo máa sọ nípa ìfẹ́ ńlá OLUWA lemọ́lemọ́,

n óo máa kọrin ìyìn rẹ̀;

nítorí gbogbo ohun tí OLUWA ti fún wa,

ati oore ńlá tí ó ṣe fún ilé Israẹli,

tí ó ṣe fún wọn nítorí àánú rẹ̀,

ati gẹ́gẹ́ bí ọpọlọpọ ìfẹ́ rẹ̀ tí kìí yẹ̀.

8 OLUWA ní, “Dájúdájú eniyan mi mà ni wọ́n,

àwọn ọmọ tí kò ní hùwà àgàbàgebè.”

Ó sì di Olùgbàlà wọn.

9 Ninu gbogbo ìyà tí wọ́n jẹ, òun pẹlu wọn ni,

angẹli iwájú rẹ̀ sì gbà wọ́n là.

Nítorí ìfẹ́ ati àánú rẹ̀, ó rà wọ́n pada.

Ó fà wọ́n sókè, ó sì gbé wọn ní gbogbo ìgbà àtijọ́.

10 Ṣugbọn wọ́n hùwà ọlọ̀tẹ̀:

wọ́n sì mú Ẹ̀mí Mímọ́ rẹ̀ bínú.

Nítorí náà ó di ọ̀tá wọn,

ó sì dojú ìjà kọ wọ́n.

11 Ṣugbọn ó ranti ìgbà àtijọ́,

ní àkókò Mose, iranṣẹ rẹ̀.

Wọ́n bèèrè pé,

ẹni tí ó kó wọn la òkun já dà?

Olùṣọ́-aguntan agbo rẹ̀,

tí ó fi Ẹ̀mí Mímọ́ rẹ̀ sáàrin wọn?

12 Ẹni tí ó gbé agbára rẹ̀ tí ó lógo wọ Mose,

tí ó pín òkun níyà níwájú wọn,

kí orúkọ rẹ̀ lè lókìkí títí lae.

13 Ó mú wọn la ibú omi kọjá, bí ẹṣin ninu aṣálẹ̀;

wọ́n rìn, wọn kò fẹsẹ̀ kọ.

14 Wọ́n rìn wọnú àfonífojì bíi mààlúù,

Ẹ̀mí OLUWA sì fún wọn ní ìsinmi.

Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe darí àwọn eniyan rẹ̀,

kí ó lè gba ògo fún orúkọ rẹ̀.

Adura fún Àánú ati Ìrànlọ́wọ́

15 Bojúwo ilẹ̀ láti ọ̀run,

láti ibùgbé rẹ mímọ́ tí ó lógo.

Ìtara rẹ dà? Agbára rẹ dà?

O ti dáwọ́ ìfẹ́ ati àánú rẹ dúró lára wa ni?

16 Ìwọ ni baba wa.

Bí Abrahamu kò tilẹ̀ mọ̀ wá,

tí Israẹli kò sì dá wa mọ̀.

Ìwọ OLUWA ni baba wa,

Olùràpadà wa láti ìgbà àtijọ́, ni orúkọ rẹ.

17 OLUWA kí ló dé tí o fi jẹ́ kí á ṣìnà, kúrò lọ́dọ̀ rẹ;

tí o sé ọkàn wa lé, tí a kò fi bẹ̀rù rẹ?

Pada sọ́dọ̀ wa nítorí àwọn iranṣẹ rẹ,

nítorí àwọn ẹ̀yà Israẹli tíí ṣe ìní rẹ.

18 Fún ìgbà díẹ̀, ilé mímọ́ rẹ jẹ́ ti àwa eniyan mímọ́ rẹ;

ṣugbọn àwọn ọ̀tá wa ti wó o lulẹ̀.

19 A wá dàbí àwọn tí o kò jọba lórí wọn rí,

àní, bí àwọn tí a kò fi orúkọ rẹ pè.

Categories
AISAYA

AISAYA 64

1 Ò bá jẹ́ fa awọsanma ya kí o sì sọ̀kalẹ̀,

kí àwọn òkè ńlá máa mì tìtì níwájú rẹ;

2 bí ìgbà tí iná ń jó igbó ṣúúrú,

tí iná sì ń mú kí omi hó.

Kí orúkọ rẹ di mímọ̀ fún àwọn ọ̀tá rẹ,

kí àwọn orílẹ̀-èdè lè máa gbọ̀n níwájú rẹ!

3 Nígbà tí o bá ṣe nǹkan tí ó bani lẹ́rù,

tí ẹnikẹ́ni kò retí,

o sọ̀kalẹ̀, àwọn òkè ńlá sì mì tìtì níwájú rẹ.

4 Láti ìgbà àtijọ́, ẹnìkan kò gbọ́ rí,

bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò tíì fi ojú rí Ọlọrun mìíràn lẹ́yìn rẹ,

tí ń ṣe irú nǹkan wọnyi fún àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé e.

5 Ò máa ran àwọn tí ń fi inú dídùn ṣiṣẹ́ òdodo lọ́wọ́,

àwọn tí wọn ranti rẹ ninu ìgbé ayé wọn,

o bínú, nítorí náà a dẹ́ṣẹ̀,

a ti wà ninu ẹ̀ṣẹ̀ wa tipẹ́.

Ǹjẹ́ a óo rí ìgbàlà?

6 Gbogbo wa dàbí aláìmọ́,

gbogbo iṣẹ́ òdodo wa dàbí àkísà ẹlẹ́gbin.

Gbogbo wa rọ bí ewé,

àìdára wa sì ń fẹ́ wa lọ bí atẹ́gùn.

7 Kò sí ẹnìkan tí ń gbadura ní orúkọ rẹ,

kò sí ẹni tí ń ta ṣàṣà láti dìmọ́ ọ;

nítorí pé o ti fojú pamọ́ fún wa,

o sì ti pa wá tì nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa.

8 Sibẹsibẹ OLUWA, ìwọ ni baba wa,

amọ̀ ni wá, ìwọ sì ni amọ̀kòkò;

iṣẹ́ ọwọ́ rẹ ni gbogbo wa.

9 OLUWA má bínú pupọ jù,

má máa ranti ẹ̀ṣẹ̀ wa títí lae.

Jọ̀wọ́, ro ọ̀rọ̀ wa wò,

nítorí pé eniyan rẹ ni gbogbo wa.

10 Àwọn ìlú mímọ́ rẹ ti di aṣálẹ̀,

Sioni ti di aṣálẹ̀, Jerusalẹmu sì ti di ahoro.

11 Wọ́n ti dáná sun ilé mímọ́ wa tí ó lẹ́wà,

níbi tí àwọn baba wa ti yìn ọ́,

gbogbo ibi dáradára tí a ní, ló ti di ahoro.

12 OLUWA, ṣé o kò ní ṣe nǹkankan sí ọ̀rọ̀ yìí ni?

Ṣé o óo dákẹ́, o óo máa fìyà jẹ wá ni?

Categories
AISAYA

AISAYA 65

Ìyà tí Ọlọrun yóo fi Jẹ Àwọn Ọlọ̀tẹ̀

1 Mo ṣetán láti mú kí àwọn tí kò bèèrè mi máa wá mi,

ati láti fi ara mi han àwọn tí kò wá mi.

Mo sọ fún orílẹ̀-èdè tí kì í gbadura ní orúkọ mi pé,

“Èmi nìyí, èmi nìyí.”

2 Láti òwúrọ̀ di alẹ́, mo na ọwọ́ mi sí àwọn ọlọ̀tẹ̀ eniyan;

àwọn tí wọn ń rìn ní ọ̀nà tí kò dára,

tí wọn ń tẹ̀lé èrò ọkàn wọn,

3 tí wọn ń ṣe ohun tí yóo mú mi bínú,

níṣojú mi, nígbà gbogbo.

Wọ́n ń rúbọ ninu oríṣìíríṣìí ọgbà,

wọ́n ń sun turari lórí bíríkì.

4 Àwọn tí wọn ń jókòó sí itẹ́ òkú,

tí wọn ń dúró níbi ìkọ̀kọ̀ lóru;

àwọn tí wọn ń jẹ ẹran ẹlẹ́dẹ̀,

tí ìṣaasùn ọbẹ̀ wọn sì kún fún ẹran aláìmọ́.

5 Wọn á máa ké pé, “Yàgò lọ́nà. Má fara kàn mí,

nítorí mo jẹ́ ẹni mímọ́ jù ọ́ lọ.”

Ṣugbọn bí èéfín ni irú wọn rí ní ihò imú mi,

bí iná tí ó ń jó lojoojumọ.

6 Wò ó! A ti kọ ọ́ sílẹ̀ níwájú mi pé,

“N kò ní dákẹ́, ṣugbọn n óo gbẹ̀san.

7 N óo gbẹ̀san gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wọn lára wọn,

ati ti àwọn baba wọn.

Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

Nítorí pé wọ́n ń sun turari lórí àwọn òkè ńlá,

wọ́n sì ń fi mí ṣẹ̀sín lórí àwọn òkè kéékèèké.

N óo san ẹ̀san iṣẹ́ wọn àtẹ̀yìnwá fún wọn.

8 “Bí eniyan tíí wòye pé ọtí wà lára ìdì èso àjàrà,

tí wọn sìí sọ pé, ‘Ẹ má bà á jẹ́,

nítorí ohun rere wà ninu rẹ̀,’

bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe nítorí iranṣẹ mi,

n kò ní pa gbogbo wọn run.

9 N óo mú kí arọmọdọmọ jáde lára Jakọbu,

àwọn tí yóo jogún òkè ńlá mi yóo sì jáde láti ara Juda.

Àwọn tí mo ti yàn ni yóo jogún rẹ̀,

àwọn iranṣẹ mi ni yóo sì máa gbé ibẹ̀.

10 Ilé Ṣaroni yóo di ibùjẹ ẹran,

àfonífojì Akori yóo sì di ibi tí àwọn ẹran ọ̀sìn yóo máa dùbúlẹ̀ sí,

fún àwọn eniyan mi, tí wọ́n wá mi.

11 “Ṣugbọn níti ẹ̀yin tí ẹ kọ mí sílẹ̀,

tí ẹ gbàgbé Òkè Mímọ́ mi,

tí ẹ tẹ́ tabili sílẹ̀ fún Gadi, oriṣa Oríire,

tí ẹ̀ ń po àdàlú ọtí fún Mẹni, oriṣa Àyànmọ́.

12 N óo fi yín fún ogun pa,

gbogbo yín ni ẹ óo sì bọ́ sọ́wọ́ àwọn apànìyàn;

nítorí pé nígbà tí mo pè yín, ẹ kò dáhùn,

nígbà tí mo sọ̀rọ̀, ẹ kò gbọ́,

ẹ ṣe nǹkan tí ó burú lójú mi;

ẹ yan ohun tí inú mi kò dùn sí.

13 Wò ó, àwọn iranṣẹ mi yóo máa rí oúnjẹ jẹ,

ṣugbọn ebi yóo máa pa yín;

àwọn iranṣẹ mi yóo mu waini,

ṣugbọn òùngbẹ yóo máa gbẹ yín.

Àwọn iranṣẹ mi yóo máa yọ̀,

ṣugbọn ìtìjú yóo máa ba yín.

14 Àwọn iranṣẹ mi yóo máa kọrin nítorí inú wọn dùn,

ṣugbọn ẹ̀yin óo máa kígbe oró àtọkànwá;

ẹ óo sì máa sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn, nítorí àròkàn.

15 Orúkọ tí ẹ óo fi sílẹ̀ fún àwọn àyànfẹ́ mi

yóo di ohun tí wọn yóo máa fi gégùn-ún.

Èmi Oluwa Ọlọrun óo pa yín.

Ṣugbọn n óo pe àwọn iranṣẹ mi ní orúkọ mìíràn.

16 Dé ibi pé ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ tọrọ ibukun ní ilẹ̀ náà,

yóo máa tọrọ rẹ̀ ní orúkọ Ọlọrun òtítọ́,

ẹnikẹ́ni tí yóo bá sì búra ní ilẹ̀ náà,

orúkọ Ọlọrun òtítọ́ ni yóo máa fi búra.

Àwọn ìṣòro àtijọ́ yóo ti di ohun ìgbàgbé,

a óo sì ti fi wọ́n pamọ́ kúrò níwájú mi.”

Ayé Tuntun

17 OLUWA ní,

“Mo dá ọ̀run tuntun, ati ayé tuntun;

a kò ní ranti àwọn ohun àtijọ́ mọ́,

tabi kí wọn sọ sí eniyan lọ́kàn.

18 Ṣugbọn ẹ jẹ́ kí inú yín ó máa dùn,

kí ẹ sì máa yọ títí lae, ninu ohun tí mo dá.

Wò ó! Mo dá Jerusalẹmu ní ìlú aláyọ̀,

mo sì dá àwọn eniyan inú rẹ̀ ní onínú dídùn.

19 N óo láyọ̀ ninu Jerusalẹmu,

inú mi óo sì máa dùn sí àwọn eniyan mi.

A kò ní gbọ́ igbe ẹkún ninu rẹ̀ mọ́,

ẹnikẹ́ni kò sì ní sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn ninu rẹ̀ mọ́.

20 Ọmọ tuntun kò ní kú ní Jerusalẹmu mọ́,

àwọn àgbààgbà kò sì ní kú láìjẹ́ pé wọ́n darúgbó kùjọ́kùjọ́.

Kàkà bẹ́ẹ̀, ikú ọ̀dọ́ ni a óo máa pe ikú ẹni tí ó bá kú ní ẹni ọgọrun-un ọdún.

Bí ẹlẹ́ṣẹ̀ bá kú ní ẹni ọgọrun-un ọdún,

a óo sọ pé ó kú ikú ègún.

21 Wọn óo kọ́ ilé, wọn óo gbé inú rẹ̀;

wọn óo gbin ọgbà àjàrà, wọn óo sì jẹ èso rẹ̀.

22 Wọn kò ní kọ́lé fún ẹlòmíràn gbé,

wọn kò sì ní gbin ọgbà àjàrà fún ẹlòmíràn jẹ.

Àwọn eniyan mi yóo pẹ́ láyé bí igi ìrókò,

àwọn àyànfẹ́ mi yóo sì jèrè iṣẹ́ ọwọ́ wọn.

23 Wọn kò ní ṣe iṣẹ́ àṣedànù,

wọn kò ní bímọ fún jamba;

nítorí ọmọ ẹni tí OLUWA bukun ni wọn yóo jẹ́,

àwọn ati àwọn ọmọ wọn.

24 Kí wọn tó pè mí, n óo ti dá wọn lóhùn,

kí wọn tó sọ̀rọ̀ tán, n óo ti gbọ́ ohun tí wọ́n fẹ́ sọ.

25 Ìkookò ati ọmọ aguntan yóo jọ máa jẹ káàkiri;

kinniun yóo máa jẹ koríko bíi mààlúù,

erùpẹ̀ ni ejò yóo máa jẹ, wọn kò ní máa panilára.

Wọn kò sì ní máa panirun lórí òkè mímọ́ mi mọ́.

Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

Categories
AISAYA

AISAYA 66

OLUWA Dá àwọn Orílẹ̀-Èdè Lẹ́jọ́

1 OLUWA ní:

“Ọ̀run ni ìtẹ́ mi,

ayé ni àpótí ìtìsẹ̀ mi.

Ilé tí ẹ kọ́ fún mi dà?

Níbo sì ni ibi ìsinmi mi wà?

2 Ọwọ́ mi ni mo fi ṣe gbogbo nǹkan wọnyi,

tèmi sì ni gbogbo wọn.

Ẹni tí n óo kà kún,

ni onírẹ̀lẹ̀ ati oníròbìnújẹ́ eniyan, tí ó ń wárìrì nítorí ọ̀rọ̀ mi.

Kò Ṣeku kò Ṣẹyẹ

3 “Ati ẹni tí ó pa mààlúù rúbọ,

ati ẹni tí ó pa eniyan;

kò sí ìyàtọ̀.

Ẹni tí ó fi ọ̀dọ́ aguntan rúbọ,

kò yàtọ̀ sí ẹni tí ó lọ́ ajá lọ́rùn pa.

Ati ẹni tí ó fi ọkà rúbọ,

ati ẹni tí ó fi ẹ̀jẹ̀ ẹlẹ́dẹ̀ rúbọ,

bákan náà ni wọ́n rí.

Ẹni tí ó fi turari ṣe ẹbọ ìrántí,

kò sì yàtọ̀ sí ẹni tí ó súre níwájú oriṣa.

Wọ́n ti yan ọ̀nà tí ó wù wọ́n,

wọ́n sì ń fi tọkàntọkàn sin ohun ìríra wọn.

4 Èmi náà óo sì yan ìjìyà fún wọn,

n óo jẹ́ kí ẹ̀rù wọn pada sórí wọn.

Nítorí pé nígbà tí mo pè wọ́n, ẹnikẹ́ni wọn kò dáhùn;

nígbà tí mo sọ̀rọ̀ fún wọn, wọn kò gbọ́,

wọ́n ṣe ohun tí ó burú lójú mi,

wọ́n yan ohun tí inú mi kò dùn sí.”

5 Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ OLUWA,

ẹ̀yin tí ẹ̀ ń wárìrì nítorí ọ̀rọ̀ rẹ̀:

“Àwọn arakunrin yín tí wọn kórìíra yín,

wọ́n tì yín síta nítorí orúkọ mi;

wọ́n ní, ‘Jẹ́ kí OLUWA fi ògo rẹ̀ hàn,

kí á lè rí ayọ̀ yín.’

Ṣugbọn àwọn ni ojú yóo tì.

6 Ẹ gbọ́ ariwo ninu ìlú,

ẹ gbọ́ ohùn kan láti inú Tẹmpili,

ohùn OLUWA ni,

ó ń san ẹ̀san fún àwọn ọ̀tá rẹ̀.

7 “Kí ó tó bẹ̀rẹ̀ sí rọbí, ó ti bímọ.

Kí ìrora obí tó mú un,

ó ti bí ọmọkunrin kan.

8 Ta ló gbọ́ irú èyí rí?

Ta ló rí irú rẹ̀ rí?

Ǹjẹ́ a lè bí ilẹ̀ ní ọjọ́ kan,

tabi kí á bí orílẹ̀-èdè kan ní ọjọ́ kan?

Ní kété tí Sioni bẹ̀rẹ̀ sí rọbí,

ni ó bí àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin.

9 Ṣé mo lè jẹ́ kí eniyan máa rọbí,

kí n má jẹ́ kí ó bímọ bí?

Èmi OLUWA, tí mò ń mú kí eniyan máa bímọ,

ṣé, mo jẹ́ sé eniyan ninu?”

10 Ẹ bá Jerusalẹmu yọ̀, kí inú yín dùn nítorí rẹ̀,

gbogbo ẹ̀yin tí ẹ fẹ́ràn rẹ̀,

ẹ bá a yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀,

gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń ṣọ̀fọ̀ nítorí rẹ̀.

11 Kí ẹ lè mu àmutẹ́rùn, ninu wàrà rẹ̀ tí ń tuni ninu;

kí ẹ lè ní ànítẹ́rùn pẹlu ìdùnnú,

ninu ọpọlọpọ ògo rẹ̀.

12 Nítorí OLUWA ní:

“N óo tú ibukun sórí rẹ̀,

bí ìgbà tí odò bá ń ṣàn.

N óo da ọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè lé e lọ́wọ́,

bí odò tí ò ṣàn kọjá bèbè.

Yóo dà yín sẹ́gbẹ̀ẹ́ bí ọmọ tí ń mu ọmú,

ẹ óo máa ṣeré lórí orúnkún rẹ̀.

13 N óo rẹ̀ yín lẹ́kún bí ọmọ tí ìyá rẹ̀ rẹ̀ lẹ́kún,

bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe tù yín ninu ní Jerusalẹmu.

14 Ẹ óo rí i, inú yín yóo dùn, egungun yín yóo sọjí,

bí ìgbà tí koríko bá rúwé.

Gbogbo eniyan yóo sì mọ̀ pé ọwọ́ OLUWA wà lára àwọn iranṣẹ rẹ̀,

ati pé inú bí i sí àwọn ọ̀tá rẹ̀.”

15 Wò ó! OLUWA ń bọ̀ ninu iná,

kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ yóo dàbí ìjì,

láti fi ìrúnú san ẹ̀san,

yóo sì fi ahọ́n iná báni wí.

16 Nítorí pé iná ni OLUWA yóo fi ṣe ìdájọ́,

idà ni yóo fi ṣe ìdájọ́ fún gbogbo eniyan;

àwọn tí OLUWA yóo fi idà pa yóo sì pọ̀.

17 OLUWA ní, “Àwọn tí wọ́n ya ara wọn sọ́tọ̀, tí wọ́n ya ara wọn sí mímọ́, wọ́n ń lọ bọ̀rìṣà ninu àgbàlá, wọ́n ń jó ijó oriṣa, wọ́n ń jẹ ẹran ẹlẹ́dẹ̀, ati àwọn ohun ìríra, ati èkúté! Gbogbo wọn ni yóo ṣègbé papọ̀.

18 Nítorí mo mọ iṣẹ́ ọwọ́ wọn ati èrò ọkàn wọn. Mò ń bọ̀ wá gbá gbogbo orílẹ̀-èdè ati ẹ̀yà jọ. Nígbà tí wọ́n bá dé, wọ́n óo rí ògo mi.

19 “N óo sì gbé àmì kan kalẹ̀ láàrin wọn. N óo rán àwọn tí ó yè lára wọn sí àwọn orílẹ̀-èdè; àwọn bíi: Taṣiṣi, Puti, ati Ludi, ilẹ̀ àwọn tafàtafà, ati Tubali ati Jafani, ati àwọn erékùṣù tí ó jìnnà réré; àwọn tí kò tíì gbọ́ òkìkí mi, tí wọn kò sì tíì rí ògo mi rí. Wọn óo sì ròyìn ògo mi láàrin àwọn orílẹ̀-èdè.

20 Wọn óo sì kó gbogbo àwọn ará yín bọ̀ láti orílẹ̀-èdè gbogbo, wọn óo kó wọn wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ fún OLUWA. Wọn óo máa bọ̀ lórí ẹṣin, lórí kẹ̀kẹ́-ogun, lórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ati ràkúnmí, wọn óo máa wá sí ìlú Jerusalẹmu, òkè mímọ́ mi, bí àwọn ọmọ Israẹli yóo ti máa mú ẹbọ ohun jíjẹ wọn wá sí ilé OLUWA, ninu àwo tí ó mọ́.

21 N óo mú ninu wọn, n óo fi ṣe alufaa ati ọmọ Lefi.

22 “Bí ọ̀run tuntun ati ayé tuntun tí n óo dá, yóo ṣe máa wà níwájú mi, bẹ́ẹ̀ ni arọmọdọmọ ati orúkọ rẹ̀ yóo máa wà.

23 Láti oṣù tuntun dé oṣù tuntun, ati láti ọjọ́ ìsinmi kan dé ekeji, ni gbogbo eniyan yóo máa wá jọ́sìn níwájú mi. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

24 Wọn óo jáde, wọn óo sì fojú rí òkú àwọn tí ó ṣọ̀tẹ̀ sí mi; nítorí ìdin tí ń jẹ wọ́n kò ní kú, bẹ́ẹ̀ ni iná tí ń jó wọn kò ní kú; wọn óo sì jẹ́ ohun ìríra lójú gbogbo eniyan.”