Categories
AISAYA

AISAYA 50

1 OLUWA ní:

OLUWA ní:

“Ìwé ìkọ̀sílẹ̀ tí mo fi kọ àwọn eniyan mi sílẹ̀ dà?

Ta ni mo tà yín fún,

tí mo jẹ lówó?

Ẹ wò ó! Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yín ni a ṣe tà yín,

nítorí àìdára yín ni mo ṣe kọ̀ yín sílẹ̀.

2 “Kí ló dé tí mo wá àwọn eniyan mi tí n kò rí ẹnìkan;

mo pè, ẹnikẹ́ni kò dá mi lóhùn?

Ṣé n kò lágbára tó láti rà wọ́n pada ni;

àbí n kò lágbára láti gba ni là?

Wò ó! Ìbáwí lásán ni mo fi gbẹ́ omi òkun,

tí mo sì fi sọ odò tí ń ṣàn di aṣálẹ̀,

omi wọn gbẹ,

òùngbẹ gbẹ àwọn ẹja inú wọn pa,

wọ́n kú, wọ́n sì ń rùn.

3 Mo da òkùnkùn bo ojú ọ̀run bí aṣọ,

mo ṣe aṣọ ọ̀fọ̀ ní ìbora fún wọn.”

Ìgbọràn Iranṣẹ OLUWA

4 OLUWA Ọlọrun ti fi ọ̀rọ̀ ìmọ̀ sí mi lẹ́nu.

Kí n lè mọ bí a tií gba àwọn tí ọkàn wọn rẹ̀wẹ̀sì níyànjú.

Ojoojumọ ni ó ń ṣí mi létí láràárọ̀,

kí n lè máa gbọ́rọ̀ bí àwọn akẹ́kọ̀ọ́.

5 OLUWA Ọlọrun ti ṣí mi létí,

n kò sì ṣe oríkunkun,

tabi kí n pada sẹ́yìn.

6 Mo tẹ́ ẹ̀yìn sílẹ̀ fún àwọn tí ń nani lẹ́gba;

mo sì kọ ẹ̀rẹ̀kẹ́ sí àwọn tí ń fa eniyan ní irùngbọ̀n tu.

N kò fojú pamọ́ nítorí ẹ̀gàn,

bẹ́ẹ̀ ni n kò gbójú sá fún itọ́ títu síni lójú.

7 OLUWA Ọlọrun ń ràn mí lọ́wọ́,

nítorí náà ojú kò tì mí;

nítorí náà mo múra gírí,

mo jẹ́ kí ojú mi le koko,

mo sì mọ̀ pé ojú kò ní tì mí.

8 Ẹni tí yóo dá mi láre wà nítòsí,

ta ló fẹ́ bá mi jà?

Ta ló fẹ́ fi ẹ̀sùn kàn mí?

Kí olúwarẹ̀ súnmọ́ tòsí mi,

kí á jọ kojú ara wa?

9 Wò ó! OLUWA Ọlọrun ń ràn mí lọ́wọ́,

ta ni yóo dá mi lẹ́bi?

Gbogbo wọn ni yóo gbọ̀n dànù bí aṣọ,

kòkòrò yóo sì jẹ wọ́n.

10 Ta ló bẹ̀rù OLUWA ninu yín,

tí ń gbọ́ràn sí iranṣẹ rẹ̀ lẹ́nu,

tí ń rìn ninu òkùnkùn,

tí kò ní ìmọ́lẹ̀,

ṣugbọn sibẹ, tí ó gbẹ́kẹ̀lé OLUWA,

tí ó fẹ̀yìn ti Ọlọrun rẹ̀.

11 Gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń dáná,

tí ẹ tan iná yí ara yín ká,

ẹ máa rìn lọ ninu iná tí ẹ dá;

ẹ máa la iná tí ẹ fi yí ara yín ká kọjá.

Bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe fun yín.

Ẹ óo wà ninu ìrora.

Categories
AISAYA

AISAYA 51

Ọ̀rọ̀ Ìtùnú fún Jerusalẹmu

1 “Ẹ gbọ́ ẹ̀yin tí ẹ̀ ń sáré ìdáǹdè,

ẹ̀yin tí ẹ̀ ń wá OLUWA,

ẹ wo àpáta tí a mú lára rẹ̀, tí a fi gbẹ yín,

ati kòtò ibi tí a ti wà yín jáde.

2 Ẹ wo Abrahamu baba yín,

ati Sara tí ó bi yín.

Òun nìkan ni nígbà tí mo pè é,

tí mo súre fún un,

tí mo sì sọ ọ́ di ọpọlọpọ eniyan.

3 “OLUWA yóo tu Sioni ninu,

yóo tu gbogbo àwọn tí ó ṣòfò ninu rẹ̀ ninu;

yóo sì sọ aṣálẹ̀ rẹ̀ dàbí Edẹni, ọgbà OLUWA.

Ayọ̀ ati ìdùnnú ni yóo máa wà ninu rẹ̀,

pẹlu orin ọpẹ́ ati orin ayọ̀.

4 “Ẹ fetí sí mi, ẹ̀yin eniyan mi,

ẹ tẹ́tí sí mi, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè,

òfin kan yóo ti ọ̀dọ̀ mi jáde,

ìdájọ́ òdodo mi yóo jẹ́ ìmọ́lẹ̀ fún àwọn eniyan.

5 Ìdáǹdè mi súnmọ́ tòsí,

ìgbàlà mi sì ti ń yọ bọ̀.

Èmi ni n óo máa ṣe àkóso àwọn eniyan,

àwọn erékùṣù yóo gbẹ́kẹ̀lé mi,

ìrànlọ́wọ́ mi ni wọn yóo sì máa retí.

6 Ẹ gbójú sókè, ẹ wo ojú ọ̀run,

kí ẹ sì wo ayé ní ìsàlẹ̀.

Ọ̀run yóo parẹ́ bí èéfín,

ayé yóo gbó bí aṣọ,

àwọn tí ń gbé inú rẹ̀ yóo sì kú bíi kòkòrò;

ṣugbọn títí lae ni ìgbàlà mi,

ìdáǹdè mi kò sì ní lópin.

7 “Ẹ̀yin tí ẹ mọ òdodo, ẹ gbọ́ ohùn mi,

ẹ̀yin tí ẹ fi tọkàntọkàn gba òfin mi,

ẹ má bẹ̀rù ẹ̀gàn àwọn eniyan;

ẹ má sì jẹ́ kí yẹ̀yẹ́ wọn já a yín láyà.

8 Ikán yóo jẹ wọ́n bí aṣọ,

kòkòrò yóo jẹ wọ́n bí òwú;

ṣugbọn ìdáǹdè mi yóo wà títí lae,

ìgbàlà mi yóo sì wà láti ìran dé ìran.”

9 Jí, jí! Dìde, OLUWA, jí pẹlu agbára;

jí bí ìgbà àtijọ́,

bí o ti ṣe sí ìran wa látijọ́.

Ṣebí ìwọ ni o gé Rahabu wẹ́lẹwẹ̀lẹ,

tí o fi idà gún diragoni?

10 Àbí ìwọ kọ́ ni o mú kí omi òkun gbẹ,

omi inú ọ̀gbun ńlá;

tí o sọ ilẹ̀ òkun di ọ̀nà,

kí àwọn tí o rà pada lè kọjá?

11 Àwọn tí OLUWA rà pada yóo pada wá,

pẹlu orin ni wọn óo pada wá sí Sioni.

Adé ayọ̀ ni wọn óo dé sórí,

wọn óo láyọ̀, inú wọn yóo dùn;

ìbànújẹ́ ati ẹ̀dùn wọn yóo sì fò lọ.

12 “Èmi fúnra mi ni mò ń tù ọ́ ninu,

ta ni ọ́, tí o fi ń bẹ̀rù eniyan tí yóo kú?

Ìwọ ń bẹ̀rù ọmọ eniyan tí a dá, bíi koríko.

13 O gbàgbé OLUWA ẹlẹ́dàá rẹ,

tí ó ta ojú ọ̀run bí aṣọ,

tí ó fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀.

O wá ń fi gbogbo ọjọ́ ayé bẹ̀rù ibinu àwọn aninilára,

nítorí wọ́n múra tán láti pa ọ́ run?

Ibinu àwọn aninilára kò ní dé ọ̀dọ̀ rẹ mọ́.

14 Láìpẹ́, a óo tú àwọn tí a tẹ̀ lórí ba sílẹ̀.

Wọn kò ní kú, wọn kò ní wọ inú isà òkú,

wọn kò sì ní wá oúnjẹ tì.

15 “Nítorí èmi ni OLUWA, Ọlọrun rẹ,

ẹni tí ó rú òkun sókè,

tí ìgbì rẹ̀ fi ń pariwo;

OLUWA àwọn ọmọ ogun ni orúkọ mi.

16 Mo ti fi ọ̀rọ̀ mi sí ọ lẹ́nu,

mo ti pa ọ́ mọ́ lábẹ́ òjìji ọwọ́ mi.

Èmi ni mo fi ojú ọ̀run sí ipò rẹ̀,

tí mo fi àwọn ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀,

tí mo sì sọ fún ìlú Sioni pé, ‘Ẹ̀yin ni eniyan mi.’ ”

Òpin Ìjìyà Jerusalẹmu

17 Jí, jí! Dìde, ìwọ Jerusalẹmu.

Ìwọ tí o ti rí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ibinu OLUWA,

ìwọ tí OLUWA ti fi ibinu jẹ níyà,

tí ojú rẹ wá ń pòòyì.

18 Kò sí ẹni tí yóo tọ́ ọ sọ́nà,

ninu gbogbo àwọn ọmọ tí o ti bí,

kò sí ẹni tí yóo fà ọ́ lọ́wọ́,

ninu gbogbo ọmọ tí o tọ́ dàgbà.

19 Àjálù meji ló dé bá ọ,

ta ni yóo tù ọ́ ninu:

Ìsọdahoro ati ìparun, ìyàn ati ogun,

ta ni yóo tù ọ́ ninu?

20 Àárẹ̀ mú àwọn ọmọ rẹ,

wọ́n sùn káàkiri ní gbogbo òpópó,

bí ìgalà tí ó bọ́ sinu àwọ̀n.

Ibinu OLUWA rọ̀jò lé wọn lórí,

àní ìbáwí Ọlọrun rẹ.

21 Nítorí náà, ẹ̀yin tí à ń fi ìyà jẹ, ẹ gbọ́ èyí;

ẹ̀yin tí ẹ ti yó láì tíì mu ọtí,

22 Oluwa rẹ, àní OLUWA Ọlọrun rẹ, tí ń bẹ̀bẹ̀ fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn eniyan rẹ̀ ní,

“Wò ó! Mo ti gba ife àmutagbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n lọ́wọ́ rẹ,

O kò ní rí ibinu mi mọ́.

23 Àwọn tí ń dá ọ lóró ni yóo rí ibinu mi,

àwọn tí ó wí fún ọ pé,

‘Bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀ kí á gba orí rẹ kọjá;’

tí wọ́n sọ ẹ̀yìn rẹ di ilẹ̀ẹ́lẹ̀,

tí wọ́n sọ ọ́ di ojú ọ̀nà wọn, tí wọn óo máa gbà kọjá.”

Categories
AISAYA

AISAYA 52

Ọlọrun Yóo Gba Jerusalẹmu

1 Jí, Sioni, jí!

Gbé agbára rẹ wọ̀ bí aṣọ,

gbé ẹwà rẹ wọ̀ bí ẹ̀wù,

ìwọ Jerusalẹmu, ìlú mímọ́;

nítorí àwọn aláìkọlà ati aláìmọ́, kò ní wọ inú rẹ mọ́.

2 Dìde, gbọnranù kúrò ninu erùpẹ̀,

ìwọ Jerusalẹmu tí ó wà ninu ìdè.

Tú okùn tí a dè mọ́ ọ lọ́rùn kúrò,

ìwọ Sioni tí ó wà ninu ìdè.

3 Nítorí OLUWA ní, “Ọ̀fẹ́ ni a mu yín lẹ́rú, ọ̀fẹ́ náà sì ni a óo rà yín pada.

4 Lákọ̀ọ́kọ́, àwọn eniyan mi lọ ṣe àtìpó ní ilẹ̀ Ijipti, lẹ́yìn náà, àwọn ará Asiria pọ́n wọn lójú láì nídìí.

5 Ṣugbọn nisinsinyii, kí ni mo rí yìí? Wọ́n mú àwọn eniyan mi lọ lọ́fẹ̀ẹ́, àwọn alákòóso wọn ń pẹ̀gàn, orúkọ mi wá di nǹkan yẹ̀yẹ́?

6 Nítorí náà àwọn eniyan mi yóo mọ orúkọ mi, wọn óo sì mọ̀ ní ọjọ́ náà pé, èmi tí mò ń sọ̀rọ̀, èmi náà nìyí.”

7 Ẹsẹ̀ ẹni tí ń mú ìyìn rere bọ̀ ti dára tó lórí òkè,

ẹni tí ń kéde alaafia,

tí ń mú ìyìn rere bọ̀,

tí sì ń kéde ìgbàlà,

tí ń wí fún Sioni pé,

“Ọlọrun rẹ jọba.”

8 Gbọ́, àwọn aṣọ́de rẹ gbóhùn sókè,

gbogbo wọn jọ ń kọrin ayọ̀,

nítorí wọ́n jọ fi ojú ara wọn rí i,

tí OLUWA pada dé sí Sioni.

9 Ẹ jọ máa kọrin pọ̀,

gbogbo ilẹ̀ Jerusalẹmu tí a sọ di aṣálẹ̀,

nítorí OLUWA yóo tu àwọn eniyan rẹ̀ ninu,

yóo ra Jerusalẹmu pada.

10 OLUWA yóo lo agbára mímọ́ rẹ̀, lójú àwọn orílẹ̀-èdè,

gbogbo eniyan, títí dé òpin ayé, yóo sì rí ìgbàlà Ọlọrun wa.

11 Ẹ jáde, ẹ jáde ẹ kúrò níbẹ̀,

ẹ má fọwọ́ kan ohun àìmọ́ kan,

ẹ jáde kúrò láàrin rẹ̀, kí ẹ sì wẹ ara yín mọ́,

ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé ohun èlò OLUWA.

12 Nítorí pé ẹ kò ní fi ìkánjú jáde,

bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò ní sáré jáde.

Nítorí OLUWA yóo máa lọ níwájú yín,

Ọlọrun Israẹli yóo sì wà lẹ́yìn yín.

Iranṣẹ tí Ń Jìyà

13 Wò ó! Iranṣẹ mi yóo ṣe àṣeyọrí

a óo gbé e ga, a óo gbé e lékè;

yóo sì di ẹni gíga,

14 Ẹnu ti ya ọpọlọpọ eniyan nítorí rẹ̀.

Wọ́n bà á lójú jẹ́ yánnayànna,

tóbẹ́ẹ̀ tí ìrísí rẹ̀ kò fi jọ ti eniyan mọ́.

15 Bẹ́ẹ̀ ni yóo di ohun ìyanu fún ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè,

kẹ́kẹ́ yóo pamọ́ àwọn ọba wọn lẹ́nu,

nígbà tí wọ́n bá rí i,

wọn óo rí ohun tí wọn kò gbọ́ rí nípa rẹ̀,

òye ohun tí wọn kò mọ̀ rí yóo yé wọn.

Categories
AISAYA

AISAYA 53

1 Ta ló lè gba ìyìn tí a rò gbọ́?

Ta ni a ti fi agbára OLUWA hàn?

2 Ó dàgbà níwájú rẹ̀ bí nǹkan ọ̀gbìn tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ rúwé

ati bíi gbòǹgbò láti inú ilẹ̀ gbígbẹ.

Ìrísí rẹ̀ kò dára,

ojú rẹ̀ kò fanimọ́ra,

bẹ́ẹ̀ ni kò ní ẹwà tí ìbá fi wu eniyan.

3 Àwọn eniyan kẹ́gàn rẹ̀,

wọ́n sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀;

ẹni tí inú rẹ̀ bàjẹ́ tí ó sì mọ ìkáàánú ni.

Ó dàbí ẹni tí àwọn eniyan ń wò ní àwòpajúdà.

A kẹ́gàn rẹ̀, a kò sì kà á kún.

4 Nítòótọ́, ó ti gbé ìkáàánú wa lọ,

ó sì ti ru ìbànújẹ́ wa;

sibẹsibẹ a kà á sí ẹni tí a nà,

tí a sì jẹ níyà láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun.

5 Ṣugbọn wọ́n ṣá a lọ́gbẹ́ nítorí àìdára wa,

wọ́n pa á lára nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa;

ìyà tí wọ́n fi jẹ ẹ́ ni ó fún wa ní alaafia,

nínà tí a nà án ni ó mú wa lára dá.

6 Gbogbo wa ti ṣáko lọ bí aguntan,

olukuluku wa yà sí ọ̀nà tirẹ̀,

OLUWA sì ti kó ẹ̀ṣẹ̀ gbogbo wa lé e lórí.

7 Wọ́n ni í lára, wọ́n pọ́n ọn lójú,

sibẹsibẹ kò lanu sọ̀rọ̀,

wọ́n fà á lọ bí ọ̀dọ́ aguntan tí wọn ń lọ pa,

ati bí aguntan tíí yadi níwájú àwọn tí ń rẹ́ irun rẹ̀,

bẹ́ẹ̀ ni kò lanu sọ̀rọ̀.

8 Wọ́n mú un lọ tipátipá,

lẹ́yìn tí wọ́n ti dá a lẹ́jọ́,

ta ni ninu ìran rẹ̀ tí ó ṣe akiyesi pé

wọ́n ti pa á run lórí ilẹ̀ alààyè,

ati pé nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn eniyan mi, ni wọ́n ṣe nà án?

9 Wọ́n tẹ́ ẹ sí ibojì, pẹlu àwọn eniyan burúkú,

wọ́n sì sin ín pẹlu ọlọ́rọ̀,

bẹ́ẹ̀ ni kò ṣe ẹnikẹ́ni níbi,

kò sì sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn.

10 Sibẹsibẹ, ó wu OLUWA láti pa á lára,

ó sì fi í sinu ìbànújẹ́,

nígbà tí ó fi ara rẹ̀ rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀;

yóo fojú rí ọmọ rẹ̀,

ọjọ́ rẹ̀ yóo sì gùn.

Ìfẹ́ OLUWA yóo ṣẹ lọ́wọ́ rẹ̀.

11 Yóo rí èrè àníyàn ọkàn rẹ̀,

yóo sì tẹ́ ẹ lọ́rùn;

nípa ìmọ̀ rẹ̀ ni iranṣẹ mi, olódodo,

yóo dá ọpọlọpọ eniyan láre,

yóo sì ru ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

12 Nítorí náà, n óo fún un ní ìpín,

láàrin àwọn eniyan ńlá,

yóo sì bá àwọn alágbára pín ìkógun,

nítorí pé ó fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ fún ikú,

wọ́n sì kà á mọ́ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.

Sibẹsibẹ ó ru ẹ̀ṣẹ̀ ọpọlọpọ eniyan,

ó sì bẹ̀bẹ̀ fún àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.

Categories
AISAYA

AISAYA 54

Ìfẹ́ OLUWA sí Israẹli

1 Máa kọrin! Ìwọ àgàn tí kò bímọ.

Máa kọrin sókè, ìwọ tí kò rọbí rí.

Nítorí ọmọ ẹni tí ọkọ ṣátì pọ̀,

ju ọmọ ẹni tí ń gbé ilé ọkọ lọ,

OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.

2 Fẹ ààyè àgọ́ rẹ sẹ́yìn,

sì jẹ́ kí aṣọ tí ó ta sórí ibùgbé rẹ gbòòrò sí i, má ṣẹ́wọ́ kù.

Na okùn àgọ́ rẹ kí ó gùn,

kí o sì kan èèkàn rẹ̀ mọ́lẹ̀ kí ó lágbára.

3 Nítorí o óo tàn kálẹ̀, sí apá ọ̀tún ati apá òsì,

àwọn ọmọ rẹ yóo gba ìtẹ́ àwọn orílẹ̀-èdè,

wọn óo sì máa gbé àwọn ìlú tí ó ti di ahoro.

4 Má bẹ̀rù nítorí ojú kò ní tì ọ́,

má sì dààmú, nítorí a kì yóo dójú tì ọ́,

nítorí o óo gbàgbé ìtìjú ìgbà èwe rẹ,

o kò sì ní ranti ẹ̀sín ìgbà tí o jẹ́ opó mọ́.

5 Nítorí Ẹlẹ́dàá rẹ ni ọkọ rẹ,

OLUWA àwọn ọmọ ogun ni orúkọ rẹ̀.

Ẹni Mímọ́ Israẹli ni Olùràpadà rẹ,

Ọlọrun gbogbo ayé ni à ń pè é.

6 Nítorí OLUWA ti pè ọ́,

bí iyawo tí ọkọ rẹ̀ kọ̀ sílẹ̀, tí ọkàn rẹ̀ bàjẹ́,

àní, bí iyawo àárọ̀ ẹni, tí a kọ̀ sílẹ̀;

OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.

7 Mo kọ̀ ọ́ sílẹ̀ fún ìgbà díẹ̀,

ṣugbọn n óo kó ọ jọ pẹlu ọpọlọpọ àánú.

8 Mo fojú mi pamọ́ fún ọ,

fún ìgbà díẹ̀ nítorí inú mi ń ru sí ọ,

ṣugbọn nítorí ìfẹ́ àìlópin mi, n óo ṣàánú fún ọ.

Èmi OLUWA, Olùràpadà rẹ ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

9 Bí ìgbà ayé Noa ni Ọ̀rọ̀ yìí rí sí mi:

mo búra nígbà náà, pé omi Noa kò ní bo ayé mọ́lẹ̀ mọ́.

Bẹ́ẹ̀ náà ni mo búra nisinsinyii,

pé n kò ní bínú sí ọ mọ́,

pé n kò ní bá ọ wí mọ́.

10 Bí àwọn òkè ńlá tilẹ̀ ṣí kúrò,

tí a sì ṣí àwọn òkè kéékèèké nídìí,

ṣugbọn ìfẹ́ mi tí kì í yẹ̀, kò ní yẹ̀ lára rẹ,

majẹmu alaafia mi tí mo bá ọ dá kò ní yẹ̀.

Èmi OLUWA tí mo ṣàánú fún ọ ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

Ọjọ́ Iwájú Jerusalẹmu

11 OLUWA ní:

“Jerusalẹmu, ìwọ ẹni tí a pọ́n lójú, tí hílàhílo bá,

tí a kò sì tù ninu,

òkúta tí a fi oríṣìíríṣìí ọ̀dà kùn ni n óo fi kọ́ ọ,

òkúta safire ni n óo sì fi ṣe ìpìlẹ̀ rẹ.

12 Òkúta Agate ni n óo fi ṣe ṣóńṣó ilé rẹ,

òkúta dídán ni n óo fi ṣe ẹnu ọ̀nà ibodè rẹ,

àwọn òkúta olówó iyebíye ni n óo fi mọ odi rẹ.

13 “Gbogbo àwọn ọmọ rẹ ọkunrin, ni OLUWA yóo kọ́

wọn yóo sì ṣe ọpọlọpọ àṣeyọrí.

14 A óo fìdí rẹ múlẹ̀, ninu òdodo,

o óo jìnnà sí ìnira, nítorí náà ẹ̀rù kò ní bà ọ́.

O óo jìnnà sí ìpayà, nítorí kò ní súnmọ́ ọ.

15 Bí ẹnìkan bá dojú ìjà kọ ọ́, kìí ṣe èmi ni mo rán an,

ẹnikẹ́ni tó bá gbéjà kò ọ́, yóo ṣubú nítorí rẹ.”

16 OLUWA ní,

“Wò ó! Èmi ni mo dá alágbẹ̀dẹ,

tí ó fi ẹwìrì fẹ́ná,

tí ó sì rọ àwọn ohun ìjà, fún ìlò rẹ̀,

èmi náà ni mo dá apanirun,

pé kí ó máa panirun.

17 Kò sí ohun ìjà tí a ṣe láti fi bá ọ jà

tí yóo lágbára lórí rẹ.

Gbogbo ẹni tí ó bá bá ọ rojọ́ nílé ẹjọ́,

ni o óo jàre wọn.

Èyí ni ìpín àwọn iranṣẹ OLUWA,

ati ìdáláre wọn lọ́dọ̀ mi.

Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

Categories
AISAYA

AISAYA 55

Àánú Ọlọrun

1 OLUWA ní,

“Gbogbo ẹni tí òùngbẹ ń gbẹ,

ẹ máa bọ̀ níbi tí omi wà;

bí ẹ kò tilẹ̀ lówó lọ́wọ́,

ẹ wá ra oúnjẹ kí ẹ sì jẹ.

Ẹ wá ra ọtí waini láì mú owó lọ́wọ́,

kí ẹ sì ra omi wàrà, tí ẹnikẹ́ni kò díyelé.

2 Kí ló dé tí ẹ̀ ń ná owó yín lórí ohun tí kì í ṣe oúnjẹ?

Tí ẹ sì ń ṣe làálàá lórí ohun tí kì í tẹ́ni lọ́rùn?

Ẹ fetí sí ọ̀rọ̀ mi dáradára,

kí ẹ sì jẹ ohun tí ó dára,

ẹ jẹ oúnjẹ aládùn, kí inú yín ó dùn.

3 “Ẹ tẹ́tí sílẹ̀ kí ẹ súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi,

ẹ gbọ́ ohun tí mò ń wí kí ẹ lè yè.

N óo ba yín dá majẹmu ayérayé,

ìfẹ́ mi tí kì í yẹ̀ tí mo ṣe ìlérí fún Dafidi.

4 Wò ó! Mo fi í ṣe olórí fún àwọn eniyan,

olórí ati aláṣẹ àwọn orílẹ̀-èdè.

5 O óo pe àwọn orílẹ̀-èdè tí o kò mọ̀ rí,

àwọn orílẹ̀-èdè tí kò mọ̀ ọ́ rí yóo sáré wá sọ́dọ̀ rẹ,

nítorí OLUWA Ọlọrun rẹ,

ati nítorí Ẹni Mímọ́ Israẹli, tí ó ṣe ọ́ lógo.”

6 Ẹ wá OLUWA nígbà tí ẹ lè rí i,

ẹ pè é nígbà tí ó wà nítòsí.

7 Kí eniyan burúkú fi ọ̀nà ibi rẹ̀ sílẹ̀,

kí alaiṣododo kọ èrò burúkú rẹ̀ sílẹ̀,

kí ó yipada sí OLUWA,

kí OLUWA lè ṣàánú rẹ̀.

Kí ó yipada sọ́dọ̀ Ọlọrun wa,

nítorí Ọlọrun yóo dáríjì í lọpọlọpọ.

8 OLUWA ní,

“Nítorí èrò tèmi yàtọ̀ sí tiyín,

bẹ́ẹ̀ ni ọ̀nà mi yàtọ̀ sí tiyín,

9 Bí ọ̀run ṣe ga ju ayé lọ,

bẹ́ẹ̀ ni ọ̀nà mi ga ju ọ̀nà yín,

tí èrò mi sì ga ju èrò yín.

10 “Bí òjò ati yìnyín, tí ń rọ̀ láti ojú ọ̀run,

tí wọn kì í pada sibẹ mọ́,

ṣugbọn tí wọn ń bomi rin ilẹ̀,

tí ń mú kí nǹkan hù jáde;

kí àgbẹ̀ lè rí èso gbìn,

kí eniyan sì rí oúnjẹ jẹ.

11 Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ tó ń jáde lẹ́nu mi yóo rí,

kò ní pada sí ọ̀dọ̀ mi lọ́wọ́ òfo,

ṣugbọn yóo ṣe ohun tí mo fẹ́ kí ó ṣe,

yóo sì ṣe é ní àṣeyọrí.

12 “Nítorí tayọ̀tayọ̀ ni ẹ óo fi máa jáde ní Babiloni,

alaafia ni wọ́n óo fi máa sìn yín sọ́nà,

òkè ńlá ati kéékèèké yóo máa kọrin níwájú yín.

Gbogbo igi inú igbó yóo sì máa pàtẹ́wọ́,

13 igi Sipirẹsi ni yóo máa hù dípò igi ẹlẹ́gùn-ún,

igi Mitili ni yóo sì máa hù dípò ẹ̀gún ọ̀gàn,

yóo jẹ́ àmì ìrántí fún OLUWA,

ati àpẹẹrẹ ayérayé tí a kò ní parẹ́.”

Categories
AISAYA

AISAYA 56

Gbogbo Orílẹ̀-Èdè ni yóo Wà lára Àwọn Eniyan Ọlọrun

1 OLUWA ní: “Ẹ máa dá ẹjọ́ ẹ̀tọ́,

kí ẹ sì máa ṣe òdodo;

nítorí ìgbàlà mi yóo dé láìpẹ́,

ẹ óo sì rí ìdáǹdè mi.

2 Ayọ̀ ń bẹ fún gbogbo ẹni tí ó bá ń ṣe bẹ́ẹ̀,

ati fún ẹni tí ó bá ń tẹ̀lé e,

tí ó ń ṣọ́ra, tí kò rú òfin ọjọ́ ìsinmi,

tí kò sì fi ọwọ́ rẹ̀ ṣe nǹkan burúkú.”

3 Kí àjèjì tí ó faramọ́ OLUWA má sọ pé,

“Dájúdájú OLUWA yóo yà mí kúrò láàrin àwọn eniyan rẹ̀.”

Kí ìwẹ̀fà má sì sọ pé,

“Wò ó! Mo dàbí igi gbígbẹ.”

4 Nítorí OLUWA ní,

“Bí ìwẹ̀fà kan bá pa ọjọ́ ìsinmi mi mọ́,

tí ó bá ṣe ohun tí mo fẹ́,

tí ó sì di majẹmu mi mú gbọningbọnin,

5 n óo fún wọn ní ipò láàrin àgbàlá mi,

ati ìrántí tí ó dára, ju ọmọkunrin ati ọmọbinrin lọ.

Orúkọ tí kò ní parẹ́ laelae, ni n óo fún wọn.

6 “Àwọn àjèjì tí ó bá darapọ̀ mọ́ OLUWA, tí wọn ń sìn ín,

tí wọn fẹ́ràn rẹ̀, tí wọn sì ń ṣe iranṣẹ rẹ̀,

gbogbo àwọn tí ó bá pa ọjọ́ ìsinmi mọ́, tí kò sọ ọ́ di ohun ìríra,

tí ó sì di majẹmu mi mú gbọningbọnin,

7 n óo mú wọn wá sí orí òkè mímọ́ mi,

n óo jẹ́ kí inú wọn máa dùn ninu ilé adura mi.

Ọrẹ sísun ati ẹbọ wọn, yóo jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà lórí pẹpẹ mi;

nítorí ilé adura fún gbogbo eniyan, ni a óo máa pe ilé mi.”

8 OLUWA Ọlọrun tí ń kó àwọn tí ogun túká ní Israẹli jọ sọ pé,

“N óo tún kó àwọn mìíràn jọ,

kún àwọn tí mo ti kọ́ kó jọ.”

A ti Dá Àwọn Olórí Israẹli lẹ́bi

9 Gbogbo ẹ̀yin orílẹ̀-èdè láti òkèèrè, ẹ máa bọ̀,

gbogbo yín ẹ máa bọ̀ bí ẹranko inú ìgbẹ́, ẹ wá jẹ àjẹrun.

10 Afọ́jú ni àwọn aṣọ́de Israẹli

gbogbo wọn kò mọ nǹkankan.

Ajá tí ó yadi ni wọ́n,

wọn kò lè gbó;

oorun ni wọ́n fẹ́ràn.

Wọn á dùbúlẹ̀, wọn á máa lá àlá.

11 Wọ̀bìà ni wọ́n, alájẹkì,

wọn kì í yó.

Àwọn olùdarí wọn pàápàá kò mọ nǹkankan.

Gbogbo wọn ti tẹ̀ sí ọ̀nà ara wọn,

olukuluku wọn ń wá èrè fún ara rẹ̀.

12 Wọn á máa sọ pé: “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á mu waini,

ẹ jẹ́ kí á mu ọtí líle ní àmuyó,

bí òní ṣe rí ni ọ̀la yóo rí, yóo dùn tayọ.”

Categories
AISAYA

AISAYA 57

OLUWA Dá Ìwà Ìbọ̀rìṣà Israẹli lẹ́bi

1 Olódodo ń ṣègbé,

kò sí ẹni tí ó fi ọkàn sí i.

A mú àwọn olótìítọ́ kúrò, kò sì sí ẹni tí ó yé,

pé à ń yọ olódodo kúrò ninu ìdààmú ni.

2 Àwọn tí ń rìn ní ọ̀nà òtítọ́, wọn óo wà ní alaafia,

wọn óo máa sinmi lórí ibùsùn wọn.

3 Ẹ̀yin ọmọ oṣó wọnyi,

ẹ súnmọ́bí fún ìdájọ́,

ẹ̀yin ọmọ alágbèrè ati panṣaga.

4 Ta ni ẹ̀ ń fi ṣe ẹlẹ́yà?

Ta ni ẹ̀ ń ya ẹnu ní ìyàkuyà sí

tí ẹ yọ ṣùtì sí?

Ṣebí ọmọ ẹ̀ṣẹ̀ ni yín

irú ọmọ ẹ̀tàn;

5 ẹ̀yin tí ẹ kún fún ìṣekúṣe lábẹ́ igi Oaku,

ati lábẹ́ gbogbo igi eléwé tútù.

Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń pa àwọn ọmọ yín láàrin àfonífojì,

ati ní abẹ́ àpáta?

6 Àwọn oriṣa láàrin àwọn òkúta ọ̀bọ̀rọ́, ninu àfonífojì,

àwọn ni ẹ̀ ń sìn,

àwọn ni ò ń da ẹbọ ohun mímu lé lórí,

àwọn ni ò ń fi nǹkan jíjẹ rúbọ sí.

Ṣé àwọn nǹkan wọnyi ni yóo mú kí inú mi yọ́?

7 Lórí òkè gíga fíofío, ni o lọ tẹ́ ibùsùn rẹ sí

níbẹ̀ ni o tí ń lọ rú ẹbọ.

8 O gbé ère oriṣa kalẹ̀ sí ẹ̀yìn ìlẹ̀kùn ati ẹ̀yìn òpó ìlẹ̀kùn.

O kọ̀ mí sílẹ̀, o bọ́ sórí ibùsùn, o tẹ́ ibùsùn tí ó fẹ̀.

O wá bá àwọn tí ó wù ọ́ da ọ̀rọ̀ pọ̀,

ẹ̀ ń bá ara yín lòpọ̀.

9 O gbọ̀nà, o lọ gbé òróró fún oriṣa Moleki,

o kó ọpọlọpọ turari lọ,

o rán àwọn ikọ̀ lọ sí ilẹ̀ òkèèrè,

o sì ranṣẹ lọ sinu isà òkú pẹlu.

10 Àárẹ̀ mú ọ nítorí ìrìn àjò rẹ jìnnà,

sibẹsibẹ o kò sọ fún ara rẹ pé, “Asán ni ìrìn àjò yìí.”

Ò ń wá agbára kún agbára,

nítorí náà àárẹ̀ kò mú ọ.

11 Ta ni ń já ọ láyà,

tí ẹ̀rù rẹ̀ bà ọ́, tí o fi purọ́;

tí o kò ranti mi, tí o kò sì ronú nípa mi?

Ṣé nítorí mo ti dákẹ́ fún ìgbà pípẹ́,

ni o kò fi bẹ̀rù mi?

12 N óo sọ nípa òdodo rẹ ati iṣẹ́ ọwọ́ rẹ,

ṣugbọn wọn kò ní lè ràn ọ́ lọ́wọ́.

13 Nígbà tí o bá kígbe,

kí àwọn ère tí o kó jọ gbà ọ́.

Atẹ́gùn lásán ni yóo gbé gbogbo wọn lọ

Afẹ́fẹ́ ni yóo fẹ́ wọn lọ.

Ṣugbọn ẹni tí ó bá sá di mí,

ni yóo ni ilẹ̀ náà,

òun ni yóo sì jogún òkè mímọ́ mi.

Ọlọrun Ṣe Ìlérí Ìrànlọ́wọ́ ati Ìwòsàn

14 OLUWA ní, “Ẹ la ọ̀nà, ẹ la ọ̀nà, ẹ tún ọ̀nà ṣe,

ẹ mú gbogbo ohun ìkọsẹ̀ kúrò lọ́nà àwọn eniyan mi.”

15 Nítorí Ẹni Gíga, tí ó ga jùlọ,

ẹni tí ń gbé ninu ayérayé, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Mímọ́:

òun ni ó ní, “Ibi gíga ati mímọ́ ni mò ń gbé lóòótọ́,

ṣugbọn mo wà pẹlu àwọn oníròbìnújẹ́ ọkàn ati àwọn onírẹ̀lẹ̀.

Láti sọ ọkàn wọn jí.

16 Nítorí n kò ní máa jà títí ayé,

tabi kí n máa bínú nígbà gbogbo:

nítorí láti ọ̀dọ̀ mi ni ẹ̀mí ti ń jáde,

Èmi ni mo dá èémí ìyè.

17 Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ojúkòkòrò rẹ̀, inú bí mi,

mo jẹ ẹ́ níyà, mo fojú pamọ́, inú sì bí mi;

sibẹ ó túbọ̀ ń ṣìnà sí i ni, ó ń ṣe tinú rẹ̀.

18 Mo ti rí bí ó ti ń ṣe,

ṣugbọn n óo ṣì wò ó sàn;

n óo máa darí rẹ̀, n óo tù ú ninu,

n óo sì fún àwọn tí ó bá ń ṣọ̀fọ̀ ní Israẹli ní orin ayọ̀.

19 Alaafia ni, alaafia ni fún àwọn tí ó wà ní òkèèrè,

ati àwọn tí ó wà nítòsí;

n óo sì wò wọ́n sàn.

20 Ṣugbọn àwọn eniyan burúkú dàbí ríru omi òkun,

nítorí òkun kò lè sinmi,

omi rẹ̀ a sì máa rú pàǹtí ati ẹrẹ̀ sókè.

21 Kò sí alaafia fún àwọn eniyan burúkú.”

Ọlọrun mi ló sọ bẹ́ẹ̀.

Categories
AISAYA

AISAYA 58

Ààwẹ̀ Tòótọ́

1 “Kígbe sókè, má dákẹ́,

ké sókè bíi fèrè ogun,

sọ ìrékọjá àwọn eniyan mi fún wọn ní àsọyé,

sọ ẹ̀ṣẹ̀ ilé Jakọbu fún wọn.

2 Nítòótọ́ ni wọ́n ń wá mi lojoojumọ,

wọ́n sì fẹ́ mọ ìlànà mi,

wọ́n ṣe bí orílẹ̀-èdè tí ó mọ òdodo,

tí kò kọ òfin Ọlọrun wọn sílẹ̀.

Wọ́n ń bèèrè ìdájọ́ òdodo lọ́dọ̀ mi,

wọ́n ní ìfẹ́ ati súnmọ́ Ọlọrun.”

3 Wọ́n ń bèèrè pé, “Kí ló dé tí à ń gbààwẹ̀, ṣugbọn tí OLUWA kò rí wa?

Tí à ń fìyà jẹ ara wa, ṣugbọn tí kò náání wa?”

OLUWA wí pé,

“Ìdí rẹ̀ ni pé,

nígbà tí ẹ bá ń gbààwẹ̀, ẹ̀ máa ṣe ìfẹ́ ọkàn yín.

Ẹ̀ sì máa ni gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ yín lára.

4 Ẹ̀ ń kún fún ìjà ati asọ̀ ní àkókò ààwẹ̀ yín,

ẹ̀ ń lu ara yín ní ìlù ìkà.

Irú ààwẹ̀ tí ẹ̀ ń gbà yìí kò ní jẹ́ kí Ọlọrun gbọ́ ohùn yín lọ́run.

5 Ṣé irú ààwẹ̀ tí mo yàn nìyí, ọjọ́ tí eniyan yóo rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ lásán?

Ṣé kí eniyan lè doríkodò bíi koríko etí odò nìkan ni?

Tabi kí ó lè jókòó lórí aṣọ ọ̀fọ̀ ati eérú nìkan?

Ṣé èyí ni ẹ̀ ń pè ní ààwẹ̀, ati ọjọ́ tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ OLUWA?

6 “Ṣebí irú ààwẹ̀ tí mo yàn ni pé:

kí á tú ìdè ìwà burúkú,

kí á yọ irin tí a fi di igi àjàgà;

kí á dá àwọn tí ìyà ń jẹ sílẹ̀ lọ́fẹ̀ẹ́,

kí á já gbogbo àjàgà?

7 Àní kí ẹ fún ẹni tí ebi ń pa ní oúnjẹ,

kí ẹ mú àwọn òtòṣì aláìnílé wá sinu ilé yín,

bí ẹ bá rí ẹnikẹ́ni ní ìhòòhò, kí ẹ fi aṣọ bò ó,

kí ẹ má sì fojú pamọ́ fún ẹni tí ó jẹ́ ẹbí yín.

8 “Nígbà náà ni ìmọ́lẹ̀ yín yóo tàn bí ìgbà tí ilẹ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ mọ́,

ara yín yóo sì tètè yá.

Òdodo yín yóo máa tàn níwájú yín.

Ògo mi yóo ṣe ààbò lẹ́yìn yín.

9 Ẹ óo ké pè mí nígbà náà,

n óo sì da yín lóhùn.

Ẹ óo kígbe pè mí,

n óo sì dáhùn pé, ‘Èmi nìyí.’

“Bí ẹ bá mú àjàgà kúrò láàrin yín,

tí ẹ kò fi ìka gún ara yín nímú mọ́,

tí ẹ kò sì sọ ọ̀rọ̀ ibi mọ́.

10 Bí ẹ bá ṣe làálàá láti fún ẹni tí ebi ń pa ní oúnjẹ,

tí ẹ sì wá ọ̀nà ìtẹ́lọ́rùn fún ẹni tí ìyà ń jẹ,

ìmọ́lẹ̀ yín yóo tàn ninu òkùnkùn,

òkùnkùn biribiri yín yóo dàbí ọ̀sán.

11 N óo máa tọ yín sọ́nà nígbà gbogbo,

n óo fi nǹkan rere tẹ yín lọ́rùn;

n óo mú kí egungun yín ó le,

ẹ óo sì dàbí ọgbà tí à ń bomi rin,

ati bí orísun omi, tí omi rẹ̀ kì í gbẹ.

12 Ẹ óo tún odi yín tí ó ti wó lulẹ̀ mọ,

ẹ óo sì gbé àwọn ìpilẹ̀ṣẹ̀ àtijọ́ dìde.

Àwọn eniyan yóo máa pè yín ní alátùn-únṣe ibi tí odi ti wó,

alátùn-únṣe òpópónà àdúgbò fún gbígbé.

Èrè Pípa Ọjọ́ Ìsinmi mọ́

13 “Bí ẹ bá dẹ́kun láti máa ba ọjọ́ ìsinmi jẹ́,

tí ẹ kò sì máa ṣe ìfẹ́ inú yín lọ́jọ́ mímọ́ mi;

bí ẹ bá pe ọjọ́ ìsinmi ní ọjọ́ ìdùnnú,

tí ẹ pe ọjọ́ mímọ́ OLUWA ní ọjọ́ ológo;

bí ẹ bá yẹ́ ẹ sí, tí ẹ kò yà sí ọ̀nà tiyín,

tí ẹ kò máa ṣe ìfẹ́ inú ara yín,

tabi kí ẹ máa sọ̀rọ̀ àhesọ;

14 nígbà náà ni inú yín yóo máa dùn láti sin èmi OLUWA,

n óo gbe yín gun orí òkè ilẹ̀ ayé,

n óo sì mu yín jogún Jakọbu, baba ńlá yín.

Èmi OLUWA ni ó sọ bẹ́ẹ̀.”

Categories
AISAYA

AISAYA 59

Wolii Lòdì sí Ẹ̀ṣẹ̀ Àwọn Eniyan

1 Wò ó! Agbára OLUWA kò dínkù, tí ó fi lè gbani là,

etí rẹ̀ kò di, tí kò fi ní gbọ́.

2 Ṣugbọn ẹ̀ṣẹ̀ yín ni ó fa ìyapa láàrin ẹ̀yin ati Ọlọrun yín,

àìdára yín ni ó mú kí ó fojú pamọ́ fun yín,

tí kò fi gbọ́ ẹ̀bẹ̀ yín.

3 Ìpànìyàn ti sọ ọwọ́ yín di aláìmọ́,

ọwọ́ yín kún fún ẹ̀ṣẹ̀, ẹ̀ ń purọ́,

ẹ sì ń fi ẹnu yín sọ ọ̀rọ̀ burúkú.

4 Kò sí ẹni tí ó ń pe ẹjọ́ àre,

kò sì sí ẹni tí ó ń rojọ́ òdodo.

Ẹjọ́ òfo ni ẹ gbójú lé.

Ẹ kún fún irọ́ pípa, ìkà ń bẹ ninu yín,

iṣẹ́ burúkú sì ń bẹ lọ́wọ́ yín.

5 Ẹ̀ ń bá paramọ́lẹ̀ pa ẹyin rẹ̀,

ẹ sì ń ran òwú aláǹtakùn,

ẹni tí ó bá jẹ ninu ẹyin yín yóo kú.

Bí ẹnìkan bá fọ́ ọ̀kan ninu ẹyin yín, ejò paramọ́lẹ̀ ni yóo jáde sí i.

6 Òwú aláǹtakùn yín kò lè di aṣọ,

eniyan kò ní fi iṣẹ́ ọwọ́ yín bora.

Iṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ ni iṣẹ́ yín,

ìwà ipá sì ń bẹ lọ́wọ́ yín.

7 Ẹsẹ̀ yín yá sí ọ̀nà ibi,

ẹ sì yára sí àtipa aláìṣẹ̀.

Èrò ẹ̀ṣẹ̀ ni èrò ọkàn yín.

Ọ̀nà yín kún fún ìsọdahoro ati ìparun.

8 Ẹ kò mọ ọ̀nà alaafia,

kò sí ìdájọ́ òdodo ní ọ̀nà yín.

Ẹ ti mú kí ọ̀nà yín wọ́,

ẹni tó bá ba yín rìn kò ní ní alaafia.

Àwọn Eniyan Jẹ́wọ́ Ẹ̀ṣẹ̀ wọn

9 Àwọn eniyan bá dáhùn pé,

“Nítorí náà ni ìdájọ́ òtítọ́ fi jìnnà sí wa,

tí òdodo kò sì fi dé ọ̀dọ̀ wà.

Ìmọ́lẹ̀ ni à ń retí, ṣugbọn òkùnkùn ló ṣú,

ìtànṣán oòrùn ni à ń retí, ṣugbọn ìkùukùu ni ó bolẹ̀.

10 À ń táràrà lára ògiri bí afọ́jú,

à ń táràrà bí ẹni tí kò lójú.

À ń kọsẹ̀ lọ́sàn-án gangan,

bí ẹni tí ó jáde ní àfẹ̀mọ́júmọ́

a dàbí òkú láàrin àwọn alágbára.

11 Gbogbo wa ń bú bí ẹranko beari,

a sì ń ké igbe ẹ̀dùn bí àdàbà.

À ń retí ìdájọ́ òdodo, ṣugbọn kò sí;

à ń retí ìgbàlà, ṣugbọn ó jìnnà sí wa.

12 “Nítorí àìdára wa pọ̀ níwájú rẹ,

ẹ̀ṣẹ̀ wa sì ń jẹ́rìí lòdì sí wa;

nítorí àwọn àìdára wa wà pẹlu wa,

a sì mọ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa:

13 A ń kọjá ààyè wa, à ń sẹ́ OLUWA,

a sì ń yipada kúrò ní ọ̀nà Ọlọrun wa.

Ọ̀rọ̀ ìninilára ati ọ̀tẹ̀ ni à ń sọ,

èrò ẹ̀tàn ní ń bẹ lọ́kàn wa, ọ̀rọ̀ èké sì ní ń jáde lẹ́nu wa.

14 A fi ọwọ́ rọ́ ẹjọ́ ẹ̀tọ́ sẹ́yìn,

òdodo sì takété.

Òtítọ́ ti ṣubú ní gbangba ìdájọ́,

ìdúróṣinṣin kò rọ́nà wọlé.

15 Òtítọ́ di ohun àwátì,

ẹni tí ó yàgò fún iṣẹ́ ibi fi ara rẹ̀ fún ayé mú.”

OLUWA Ṣetán láti Gba Àwọn Eniyan Rẹ̀

OLUWA rí i pé kò sí ìdájọ́ òdodo,

ó sì bà á lọ́kàn jẹ́,

16 Ó rí i pé kò sí ẹnìkan tí yóo ṣe onílàjà,

ẹnu sì yà á, pé kò sí ẹnìkankan.

Ó bá fi ọwọ́ rẹ̀ ṣẹgun fún ara rẹ̀,

òdodo rẹ̀ sì gbé e dúró.

17 Ó gbé òdodo wọ̀ bí ìgbàyà,

ó fi àṣíborí ìgbàlà borí.

Ó gbé ẹ̀san wọ̀ bí ẹ̀wù,

ó fi bora bí aṣọ.

18 Yóo san ẹ̀san fún wọn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ wọn,

yóo bínú sí àwọn tí wọ́n lòdì sí i,

yóo sì san ẹ̀san fún àwọn ọ̀tá rẹ̀,

ati àwọn tí ń gbé erékùṣù.

19 Wọn óo bẹ̀rù orúkọ OLUWA láti ìwọ̀ oòrùn,

wọn óo bẹ̀rù ògo rẹ̀ láti ìlà oòrùn;

nítorí yóo wá bí ìkún omi, tí ẹ̀fúùfù láti ọ̀dọ̀ OLUWA ń taari.

20 OLUWA ní, “N óo wá sí Sioni bí Olùràpadà,

n óo wá sọ́dọ̀ àwọn ọmọ Jakọbu,

tí wọ́n yipada kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀.

21 “Majẹmu tí Èmi bá wọn dá nìyí: Ẹ̀mí mi tí mo fi le yín lórí, ati ọ̀rọ̀ mi tí mo fi si yín lẹ́nu, kò gbọdọ̀ kúrò lẹ́nu yín, ati lẹ́nu àwọn ọmọ rẹ, ati lẹ́nu arọmọdọmọ yín, láti àkókò yìí lọ ati títí laelae. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”