Categories
AISAYA

AISAYA 40

Ọ̀rọ̀ Ìtùnú fún Àwọn Ọmọ Israẹli

1 Ọlọrun yín ní, “Ẹ tù wọ́n ninu,

ẹ tu àwọn eniyan mi ninu.

2 Ẹ bá Jerusalẹmu sọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́

ẹ ké sí i pé, ogun jíjà rẹ̀ ti parí,

a ti dárí àìṣedéédé rẹ̀ jì í.

OLUWA ti jẹ ẹ́ níyà ní ìlọ́po meji nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.”

3 Ẹ gbọ́ ohùn akéde kan tí ń wí pé,

“Ẹ tún ọ̀nà OLUWA ṣe ninu aginjù,

ẹ la òpópónà títọ́ fún Ọlọrun wa ninu aṣálẹ̀.

4 Gbogbo àfonífojì ni a óo ru sókè,

a óo sì sọ àwọn òkè ńlá ati òkè kéékèèké di pẹ̀tẹ́lẹ̀:

Gbogbo ọ̀nà tí ó wọ́ ni yóo di títọ́,

ọ̀nà gbágun-gbàgun yóo sì di títẹ́jú.

5 Ògo OLUWA yóo farahàn,

gbogbo eniyan yóo sì jọ fojú rí i.

OLUWA ni ó fi ẹnu ara rẹ̀ sọ bẹ́ẹ̀.”

6 Mo gbọ́ ohùn kan tí ń wí pé, “Kígbe!”

Mo bá bèèrè pé,

“Igbe kí ni kí n ké?”

Ó ní, “Kígbe pé, koríko ṣá ni gbogbo eniyan,

gbogbo ẹwà sì dàbí òdòdó inú pápá.

7 Koríko a máa rọ, òdòdó a sì máa rẹ̀

nígbà tí OLUWA bá fẹ́ afẹ́fẹ́ lù ú.

Dájúdájú koríko ni eniyan.

8 Koríko a máa rọ,

òdòdó a sì máa rẹ̀;

ṣugbọn ọ̀rọ̀ Ọlọrun wa dúró títí lae.”

9 Gun orí òkè gíga lọ, ìwọ Sioni,

kí o máa kéde ìyìn rere.

Gbé ohùn rẹ sókè pẹlu agbára Jerusalẹmu,

ìwọ tí ò ń kéde ìyìn rere

ké sókè má ṣe bẹ̀rù;

sọ fún àwọn ìlú Juda pé,

“Ẹ wo Ọlọrun yín.”

10 Ẹ wò ó! OLUWA Ọlọrun ń bọ̀ pẹlu agbára

ipá rẹ̀ ni yóo fi máa ṣe àkóso.

Ẹ wò ó! Èrè rẹ̀ ń bẹ lọ́wọ́ rẹ̀, ẹ̀san rẹ̀ sì ń bẹ níwájú rẹ̀.

11 Yóo bọ́ agbo ẹran bí olùṣọ́-aguntan.

Yóo kó àwọn ọ̀dọ́ aguntan jọ sí apá rẹ̀,

yóo gbé wọn mọ́ àyà rẹ̀.

Yóo sì máa fi sùúrù da àwọn tí wọn lọ́mọ lẹ́yìn láàrin wọn.

OLUWA Kò Ní Àfijọ

12 Ta ló lè fi kòtò ọwọ́ wọn omi òkun?

Ta ló lè fìka wọn ojú ọ̀run,

Kí ó kó erùpẹ̀ ilẹ̀ ayé

sinu òṣùnwọ̀n?

Ta ló lè gbé àwọn òkè ńlá ati àwọn kéékèèké sórí ìwọ̀n?

13 Ta ló darí Ẹ̀mí OLUWA,

ta ló sì tọ́ ọ sọ́nà gẹ́gẹ́ bí olùdámọ̀ràn rẹ̀?

14 Ọwọ́ ta ni OLUWA ti gba ìmọ̀ràn tí ó fi ní òye,

ta ló kọ́ ọ bí wọ́n ṣe ń dájọ́ ẹ̀tọ́,

tí ó kọ́ ọ ní ìmọ̀,

tí ó sì fi ọ̀nà òye hàn án?

15 Wò ó, àwọn orílẹ̀-èdè dàbí ìkán omi kan ninu garawa omi,

ati bí ẹyọ eruku kan lórí òṣùnwọ̀n.

Ẹ wò ó, ó mú àwọn erékùṣù lọ́wọ́ bí àtíkè.

16 Gbogbo igi igbó Lẹbanoni kò tó fún iná ẹbọ,

bẹ́ẹ̀ ni ẹranko ibẹ̀ kò tó fún ẹbọ sísun.

17 Gbogbo orílẹ̀-èdè kò tó nǹkan níwájú rẹ̀,

wọn kò jámọ́ nǹkan lójú rẹ̀, òfo ni wọ́n.

18 Ta ni ẹ lè fi Ọlọrun wé,

tabi kí ni ẹ lè fi ṣe àkàwé rẹ̀?

19 Ṣé oriṣa ni! Tí oníṣẹ́ ọwọ́ ṣe;

tí alágbẹ̀dẹ wúrà yọ́ wúrà bò

tí ó sì fi fadaka ṣe ẹ̀wọ̀n fún?

20 Ẹni tí ó bá talaka, tí kò lágbára nǹkan ìrúbọ,

a wá igi tí kò lè rà, tí kò sì lè ju;

a wá agbẹ́gilére tí ó mọṣẹ́,

láti bá a gbẹ́ ère tí kò lè paradà.

21 Ṣé ẹ kò tíì mọ̀?

Ẹ kò sì tíì gbọ́?

Ṣé wọn kò sọ fun yín láti ìbẹ̀rẹ̀,

kò sì ye yín láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé, pé:

22 Òun ni ó jókòó lókè àyíká ayé,

àwọn eniyan inú rẹ̀ sì dàbí tata lójú rẹ̀.

Òun ni ó ta awọsanma bí aṣọ títa,

ó sì ta á bí àgọ́, ó ń gbébẹ̀.

23 Ẹni tí ó sọ àwọn ọba di ẹni ilẹ̀,

ó sọ àwọn olóyè ayé di asán.

24 Wọ́n fẹ́rẹ̀ má ì tíì gbìn wọ́n,

wọ́n fẹ́rẹ̀ má ì tíì ta gbòǹgbò wọlẹ̀;

nígbà tí ó fẹ́ afẹ́fẹ́ lù wọ́n,

tí wọ́n fi rọ bí ewéko,

tí ìjì sì gbé wọn lọ bí àgékù koríko.

25 Ta ni ẹ óo wá fi mí wé,

tí n óo sì dàbí rẹ̀?

Èmi Ẹni Mímọ́ ni mo bèèrè bẹ́ẹ̀.

26 Ẹ gbójú sókè kí ẹ wo ojú ọ̀run,

ta ni ó dá àwọn nǹkan tí ẹ rí wọnyi?

Ẹni tí ó kó àwọn ìràwọ̀ sójú ọ̀run bí ọmọ ogun,

tí ó ń pè wọ́n jáde lọ́kọ̀ọ̀kan,

tí ó sì mọ olukuluku mọ́ orúkọ rẹ̀.

Nítorí bí ipá rẹ̀ ti tó,

ati bí agbára rẹ̀ ti pọ̀ tó,

ẹyọ ọ̀kan ninu wọn kò di àwátì.

27 Kí ló dé, Jakọbu, tí o fi ń rojọ́?

Kí ló ṣe ọ́, Israẹli, tí o fi ń sọ pé,

“OLUWA kò mọ ohun tí ń ṣe mí,

Ọlọrun kò sì bìkítà nípa ẹ̀tọ́ mi.”

28 Ṣé o kò tíì mọ̀,

o kò sì tíì gbọ́

pé Ọlọrun ayérayé ni OLUWA,

Ẹlẹ́dàá gbogbo ayé.

Kì í rẹ̀ ẹ́, bẹ́ẹ̀ ni agara kì í dá a.

Àwámárìídìí ni òye rẹ̀.

29 A máa fún aláàárẹ̀ ní okun.

A sì máa fún ẹni tí kò lágbára ní agbára.

30 Yóo rẹ àwọn ọ̀dọ́ pàápàá, agara óo sì dá wọn,

àwọn ọdọmọkunrin yóo tilẹ̀ ṣubú lulẹ̀ patapata.

31 Ṣugbọn àwọn tí ó bá dúró de OLUWA

yóo máa gba agbára kún agbára.

Wọn óo máa fi ìyẹ́ fò lọ sókè bí ẹyẹ idì.

Wọn óo máa sáré, agara kò ní dá wọn;

wọn óo máa rìn, kò sì ní rẹ̀ wọ́n.

Categories
AISAYA

AISAYA 41

Ọlọrun fún Israẹli ní Ìdánilójú

1 “Ẹ dákẹ́ jẹ́ẹ́, kí ẹ sì gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, ẹ̀yin erékùṣù,

kí àwọn eniyan gba agbára kún agbára wọn,

kí wọ́n súnmọ́ ìtòsí, kí wọ́n sọ tẹnu wọn,

ẹ jẹ́ kí á pàdé ní ilé ẹjọ́.

2 “Ta ló gbé ẹnìkan dìde ní ìhà ìlà oòrùn?

Tí ó ń ṣẹgun ní ibikíbi tí ó bá fẹsẹ̀ tẹ̀?

Ta ló fi àwọn orílẹ̀-èdè lé e lọ́wọ́

tí ó fi lè tẹ àwọn ọba mọ́lẹ̀?

Idà rẹ̀ gé wọn bí eruku,

ọfà rẹ̀ sì tú wọn ká bí àgékù koríko.

3 A máa lépa wọn, a sì máa kọjá wọn láìléwu,

ní ọ̀nà tí ẹsẹ̀ rẹ̀ kò tẹ̀ rí.

4 Ta ló ṣe èyí?

Iṣẹ́ ọwọ́ ta sì ni?

Tí ó pe ìran dé ìran láti ìbẹ̀rẹ̀?

Èmi OLUWA ni, ẹni àkọ́kọ́ ati ẹni ìkẹyìn.

5 “Àwọn erékùṣù rí i, ẹ̀rù bà wọ́n,

gbogbo òpin ayé gbọ̀n rìrì wọ́n ti súnmọ́ tòsí, wọ́n ti dé.

6 Olukuluku ń ran ẹnìkejì rẹ̀ lọ́wọ́,

ó ń sọ fún arakunrin rẹ̀ pé, ‘Ṣara gírí.’

7 Agbẹ́gilére ń gba alágbẹ̀dẹ wúrà níyànjú

ẹni tí ń fi òòlù lu irin ń kí ẹni tí ń dán irin tí wọ́n ti rọ,

Ó ń wí pé: ‘Òjé tí a fi jó o dára.’

Wọ́n kàn án ní ìṣó,

ó le dáradára, kò le mì.

8 “Ìwọ ní tìrẹ, Israẹli iranṣẹ mi,

Jakọbu, ìwọ tí mo ti yàn,

ọmọ bíbí inú Abrahamu, ọ̀rẹ́ mi.

9 Ìwọ tí mo mú wá láti òpin ayé,

tí mo pè láti ìkangun ayé tí ó jìnnà jùlọ,

mo wí fún ọ pé, ‘Iranṣẹ mi ni ọ́,

mo ti yàn ọ́, n kò ní ta ọ́ nù.’

10 Má bẹ̀rù, nítorí mo wà pẹlu rẹ,

má fòyà, nítorí èmi ni Ọlọrun rẹ.

N óo fún ọ ní agbára, n óo sì ràn ọ́ lọ́wọ́;

ọwọ́ ọ̀tún mi, ọwọ́ ìṣẹ́gun, ni n óo fi gbé ọ ró.

11 “Gbogbo àwọn tí wọ́n fẹ́ pa ọ́ run

ni n óo dójú tì, wọn óo sì dààmú.

Àwọn tí ń bá ọ jà yóo di asán,

wọn óo sì ṣègbé.

12 O óo wá àwọn tí ń bá ọ jà tì,

o kò ní rí wọn.

Àwọn tí ó gbógun tì ọ́

yóo di òfo patapata.

13 Nítorí èmi OLUWA Ọlọrun rẹ,

ti di ọwọ́ ọ̀tún rẹ mú,

èmi ni mo sọ fún ọ pé

kí o má bẹ̀rù, n óo ràn ọ́ lọ́wọ́.”

14 Ẹ má bẹ̀rù, ẹ̀yin ọmọ Jakọbu,

bí ẹ tilẹ̀ dàbí kòkòrò lásán,

ẹ̀yin ọmọ Israẹli,

OLUWA ní òun óo ràn yín lọ́wọ́.

Ẹni Mímọ́ Israẹli ni Olùràpadà yín.

15 Ó ní, “N óo ṣe yín bí ohun èlò ìpakà titun,

tí ó mú, tí ó sì ní eyín,

ẹ óo tẹ àwọn òkè ńlá mọ́lẹ̀, ẹ óo rún wọn wómúwómú;

ẹ óo sì sọ àwọn òkè kéékèèké di fùlùfúlù.

16 Ẹ óo fẹ́ wọn bí ọkà, atẹ́gùn yóo gbé wọn lọ,

ìjì yóo sì fọ́n wọn ká.

Ẹ̀yin óo yọ̀ ninu OLUWA

ẹ óo sì ṣògo ninu Ẹni Mímọ́ Israẹli.

17 “Nígbà tí àwọn talaka ati àwọn aláìní bá ń wá omi, tí omi kò sí,

tí òùngbẹ ń gbẹ wọ́n, tí ọ̀nà ọ̀fun wọn gbẹ,

èmi OLUWA yóo dá wọn lóhùn,

èmi Ọlọrun Israẹli kò ní fi wọ́n sílẹ̀.

18 N óo ṣí odò lórí àwọn òkè,

ati orísun láàrin àwọn àfonífojì;

n óo sọ aṣálẹ̀ di adágún odò,

ilẹ̀ gbígbẹ yóo sì di orísun omi.

19 N óo gbin igi kedari sinu aṣálẹ̀,

pẹlu igi akasia ati igi mitili ati igi olifi.

N óo gbin igi sipirẹsi sinu aṣálẹ̀,

n óo gbin igi firi ati pine papọ̀.

20 Kí àwọn eniyan lè rí i, kí wọn sì mọ̀,

kí wọ́n rò ó wò, kí òye lè yé wọn papọ̀,

pé ọwọ́ OLUWA ni ó ṣe èyí,

Ẹni Mímọ́ Israẹli ni ó ṣẹ̀dá rẹ̀.”

OLUWA Pe Àwọn Ọlọrun Èké níjà

21 OLUWA, Ọba Jakọbu, ní:

“Ẹ̀yin oriṣa àwọn orílẹ̀-èdè, ẹ ro ẹjọ́ yín,

kí ẹ mú ẹ̀rí tí ó dájú wá lórí ohun tí ẹ bá ní sọ.

22 Ẹ mú wọn wá,

kí ẹ sì sọ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ fún wa;

kí ẹ sọ àwọn ohun àtijọ́ fún wa.

Kí á lè gbé wọn yẹ̀wò;

kí á lè mọ àyọrísí wọn,

tabi kí ẹ sọ àwọn ohun tí ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ fún wa.”

23 OLUWA ní, “Ẹ sọ ohun tí ń bọ̀ lẹ́yìn ọ̀la fún wa,

kí á lè mọ̀ pé oriṣa ni yín;

ẹ ṣe nǹkan rere tabi nǹkan burúkú kan,

kí á rí i, kí ẹ̀rù sì bà wá.

24 Ẹ wò ó! Òfo ni yín, òfo sì ni iṣẹ́ ọwọ́ yín,

ẹni ìríra ni ẹni tí ó bá yàn yín.

25 Mo ti gbé ẹnìkan dìde láti ìhà àríwá,

ó sì ti dé.

Láti ìlà oòrùn ni yóo ti pe orúkọ mi;

yóo máa gún àwọn ọba mọ́lẹ̀ bì ìgbà tí wọ́n gún nǹkan ninu odó,

àní, bí ìgbà tí amọ̀kòkò bá ń gún amọ̀.

26 Ta ló kéde rẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀ wá, kí á lè mọ̀,

ta ló sọ nípa rẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀

kí á lè sọ pé, ‘Olóòótọ́ ni?’

Kò sí ẹni tí ó sọ ọ́, kò sí ẹni tí ó kéde rẹ̀;

ẹnìkankan kò gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀.

27 Èmi OLUWA ni mo ti kọ́kọ́ sọ fún Sioni,

tí mo sì ròyìn ayọ̀ náà fún Jerusalẹmu.

28 Nígbà tí mo wo ààrin àwọn wọnyi, kò sí olùdámọ̀ràn kan,

tí ó lè dá mi lóhùn nígbà tí mo bá ní ìbéèrè.

29 Wò ó! Ìtànjẹ lásán ni gbogbo wọn,

òfo ni iṣẹ́ ọwọ́ wọn:

Ẹ̀fúùfù lásán ni àwọn ère tí wọ́n gbẹ́.”

Categories
AISAYA

AISAYA 42

Iranṣẹ Ọlọrun

1 OLUWA ní,

“Wo iranṣẹ mi, ẹni tí mo gbéró,

àyànfẹ́ mi, ẹni tí inú mi dùn sí.

Mo ti jẹ́ kí ẹ̀mí mi bà lé e,

yóo máa dá ẹjọ́ ẹ̀tọ́ fún àwọn orílẹ̀-èdè.

2 Kò ní kígbe, kò sì ní pariwo,

kò ní jẹ́ kí á gbọ́ ohùn rẹ̀ ní ìta gbangba.

3 Kò ní ṣẹ́ ọ̀pá ìyè tí ó tẹ̀,

bẹ́ẹ̀ ni kò ní pa iná fìtílà tí ń jò bẹ́lúbẹ́lú,

yóo fi òtítọ́ dá ẹjọ́.

4 Kò ní kùnà, bẹ́ẹ̀ ni ọkàn rẹ̀ kò ní rẹ̀wẹ̀sì,

títí yóo fi fìdí ìdájọ́ òdodo múlẹ̀ láyé.

Àwọn erékùṣù ń retí òfin rẹ̀.”

5 Ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA Ọlọrun sọ;

ẹni tí ó dá ojú ọ̀run tí ó sì ta á bí aṣọ,

tí ó tẹ ayé, ati àwọn ohun tí ń hù jáde láti inú rẹ̀;

ẹni tí ó fi èémí sinu àwọn eniyan tí ń gbé orí ilẹ̀;

tí ó sì fi ẹ̀mí fún àwọn tí ó ń rìn lórí rẹ̀.

6 Ó ní, “Èmi ni OLUWA, mo ti pè ọ́ ninu òdodo,

mo ti di ọwọ́ rẹ mú,

mo sì pa ọ́ mọ́.

Mo ti fi ọ́ ṣe majẹmu fún aráyé,

mo sì fi ọ́ ṣe ìmọ́lẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè;

7 kí o lè la ojú àwọn afọ́jú,

kí o lè yọ àwọn ẹlẹ́wọ̀n kúrò ni àhámọ́,

kí o lè yọ àwọn tí ó jókòó ninu òkùnkùn kúrò ní ọgbà ẹ̀wọ̀n.

8 “Èmi ni OLUWA, bẹ́ẹ̀ ni orúkọ mi;

n kò ní fi ògo mi fún ẹlòmíràn,

n kò sì ní fi ìyìn mi fún ère.

9 Wò ó! Àwọn nǹkan àtijọ́ ti kọjá,

àwọn nǹkan tuntun ni mò ń kéde nisinsinyii.

Kí wọn tó yọjú jáde rárá,

ni mo ti sọ fún ọ nípa wọn.”

Orin Ìyìn fún OLUWA

10 Ẹ kọ orin tuntun sí OLUWA;

ẹ kọ orin ìyìn rẹ̀ láti òpin ayé.

Ẹ̀yin èrò inú ọkọ̀ lójú agbami òkun,

ati gbogbo ohun tí ó wà ninu omi òkun;

ati àwọn erékùṣù ati àwọn tí ń gbé inú wọn.

11 Kí aṣálẹ̀ ati àwọn ìlú inú rẹ̀ kọ orin ìyìn sókè,

ati àwọn abúlé agbègbè Kedari;

kí àwọn ará ìlú Sela kọrin ayọ̀,

kí wọn máa kọrin lórí àwọn òkè.

12 Kí wọn fi ògo fún OLUWA,

kí wọn kéde ìyìn rẹ̀ ní àwọn erékùṣù.

13 OLUWA yọ jáde lọ bí alágbára ọkunrin,

ó ru ibinu rẹ̀ sókè bí ọkunrin ogun,

ó kígbe, ó sì bú ramúramù.

Ó fihàn pé alágbára ni òun níwájú àwọn ọ̀tá rẹ̀.

Ọlọrun ṣe Ìlérí láti Ran Àwọn Eniyan Rẹ̀ lọ́wọ́

OLUWA ní:

14 “Ó ti pẹ́ tí mo ti dákẹ́ jẹ́ẹ́,

mo dákẹ́ jẹ́ẹ́, mo mára dúró.

Ṣugbọn nisinsinyii, n óo kígbe,

bí obinrin tí ń rọbí lọ́wọ́.

N óo máa mí túpetúpe,

n óo máa mí hẹlẹhẹlẹ.

15 N óo sọ àwọn òkè gíga ati àwọn kéékèèké di ilẹ̀,

n óo mú kí gbogbo ewéko orí wọn gbẹ;

n óo sọ àwọn odò di erékùṣù,

n óo sì mú kí àwọn adágún omi gbẹ.

16 “N óo darí àwọn afọ́jú,

n óo mú wọn gba ọ̀nà tí wọn kò mọ̀ rí,

n óo tọ́ wọn sọ́nà,

ní ọ̀nà tí wọn kò mọ̀ rí.

N óo sọ òkùnkùn di ìmọ́lẹ̀ níwájú wọn,

n óo sì sọ àwọn ibi tí ó rí pálapàla di títẹ́jú.

N óo ṣe àwọn nǹkan,

n kò sì ní kọ̀ wọ́n sílẹ̀.

17 A óo ká àwọn tí ó gbójú lé ère lọ́wọ́ kò,

ojú yóo sì tì wọ́n patapata

àwọn tí ń wí fún ère gbígbẹ́ pé:

‘Ẹ̀yin ni Ọlọrun wa.’ ”

Israẹli Kùnà láti Kẹ́kọ̀ọ́

OLUWA ní:

18 “Gbọ́, ìwọ adití,

sì wò ó, ìwọ afọ́jú, kí o lè ríran.

19 Ta ni afọ́jú, bíkòṣe iranṣẹ mi?

Ta sì ni adití, bíkòṣe ẹni tí mo rán níṣẹ́?

Ta ni ó fọ́jú tó ẹni tí mo yà sọ́tọ̀,

tabi ta ni ojú rẹ̀ fọ́ tó ti iranṣẹ OLUWA?

20 Ó ń wo ọpọlọpọ nǹkan, ṣugbọn kò ṣe akiyesi wọn.

Etí rẹ̀ là sílẹ̀,

ṣugbọn kò gbọ́ràn.”

21 Ó wu OLUWA láti gbé òfin rẹ̀ ga

ati láti ṣe é lógo nítorí òdodo rẹ̀.

22 Ṣugbọn a ti ja àwọn eniyan wọnyi lólè,

a sì ti kó wọn lẹ́rù,

a ti sé gbogbo wọn mọ́ inú ihò ilẹ̀,

a sì ti fi wọ́n pamọ́ sinu ọgbà ẹ̀wọ̀n.

A fogun kó wọn, láìsí ẹni tí yóo gbà wọ́n sílẹ̀,

a kó wọn lẹ́rú, láìsí ẹnikẹ́ni tí yóo sọ pé:

“Ẹ dá wọn pada.”

23 Èwo ninu yín ló fetí sí èyí,

tabi tí yóo farabalẹ̀ gbọ́ nítorí ẹ̀yìn ọ̀la?

24 Ta ló fa Jakọbu lé akónilẹ́rù lọ́wọ́,

ta ló sì fa Israẹli lé àwọn ọlọ́ṣà lọ́wọ́?

Ṣebí OLUWA tí a ti ṣẹ̀ ni,

ẹni tí wọ́n kọ̀, tí wọn kò rìn ní ọ̀nà rẹ̀;

tí wọn kò sì pa òfin rẹ̀ mọ́.

25 Nítorí náà ó jẹ́ kí wọ́n rí ibinu òun,

ó sì fi agbára ogun rẹ̀ hàn wọ́n.

Ó tanná ràn án lọ́tùn-ún lósì, sibẹ kò yé e;

iná jó o, sibẹsibẹ kò fi ṣe àríkọ́gbọ́n.

Categories
AISAYA

AISAYA 43

OLUWA Ṣe Ìlérí láti Gba Àwọn Eniyan Rẹ̀ Là

1 Ṣugbọn nisinsinyii, Jakọbu,

gbọ́ nǹkan tí OLUWA ẹlẹ́dàá rẹ wí,

Israẹli, gbọ́ ohun tí ẹni tí ó dá ọ sọ.

Ó ní, “Má bẹ̀rù, nítorí mo ti rà ọ́ pada;

mo ti pè ọ́ ní orúkọ rẹ, èmi ni mo ni ọ́.

2 Nígbà tí o bá ń la ibú omi kọjá,

n óo wà pẹlu rẹ;

nígbà tí o bá la odò ńlá kọjá,

kò ní bò ọ́ mọ́lẹ̀,

nígbà tí o bá ń kọjá ninu iná, kò ní jó ọ.

Ahọ́n iná kò ní jó ọ run.

3 Nítorí èmi ni OLUWA Ọlọrun rẹ,

Ẹni Mímọ́ Israẹli, Olùgbàlà rẹ.

Mo fi Ijipti, lélẹ̀, láti rà ọ́ pada,

mo sì fi Etiopia ati Seba lélẹ̀ mo ti fi ṣe pàṣípààrọ̀ rẹ.

4 Nítorí pé o ṣọ̀wọ́n lójú mi, o níyì, mo sì fẹ́ràn rẹ,

mo fi àwọn eniyan rọ́pò rẹ;

mo sì fi ẹ̀mí àwọn orílẹ̀-èdè dípò ẹ̀mí rẹ.

5 Má bẹ̀rù nítorí mo wà pẹlu rẹ,

n óo kó àwọn ọmọ rẹ wá láti ìlà oòrùn,

n óo sì ko yín jọ láti ìwọ̀ oòrùn.

6 N óo pàṣẹ fún ìhà àríwá pé,

‘Dá wọn sílẹ̀.’

N óo sọ fún ìhà gúsù pé,

‘O kò gbọdọ̀ dá wọn dúró.’

Kó àwọn ọmọ mi ọkunrin wá láti òkèèrè,

sì kó àwọn ọmọ mi obinrin wá láti òpin ayé,

7 gbogbo àwọn tí à ń fi orúkọ mi pè,

àwọn tí mo dá fún ògo mi,

àwọn tí mo fi ọwọ́ mi ṣẹ̀dá wọn.”

Ẹlẹ́rìí OLUWA ni Israẹli

8 Ẹ mú àwọn eniyan mi jáde,

àwọn tí wọ́n ní ojú, ṣugbọn tí ojú wọn ti fọ́,

wọ́n ní etí, ṣugbọn etí wọn ti di.

9 Jẹ́ kí gbogbo orílẹ̀-èdè péjọ,

kí àwọn eniyan àgbáyé parapọ̀.

Èwo ninu wọn ni ó lè kéde irú àsọtẹ́lẹ̀ yìí,

tí ó lè fi àwọn ohun àtijọ́ hàn wá;

kí wọn pe ẹlẹ́rìí wọn wá, kí á lè mọ̀ pé ẹjọ́ wọn tọ́,

kí àwọn ẹlòmíràn lè gbọ́, kì wọn sì jẹ́rìí pé, “Òtítọ́ ni.”

10 OLUWA ní, “Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi,

ẹ̀yin ni iranṣẹ mi tí mo yàn;

kí ẹ lè mọ̀ mí, kí ẹ sì gbà mí gbọ́,

kí ó sì ye yín pé, Èmi ni.

A kò dá Ọlọrun kankan ṣáájú mi,

òmíràn kò sì ní wáyé lẹ́yìn mi.

11 “Èmi ni OLUWA,

kò sí olùgbàlà kan, yàtọ̀ sí mi.

12 Mo ti sọ̀rọ̀ ìṣípayá, mo ti gba eniyan là,

mo sì ti kéde,

nígbà tí kò sí Ọlọrun àjèjì láàrin yín;

ẹ̀yin sì ni ẹlẹ́rìí mi.

Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

13 Èmi ni Ọlọrun,

láti ìsinsìnyìí lọ, Èmi ni.

Kò sí ẹnìkan tí ó lè gba eniyan kalẹ̀ lọ́wọ́ mi:

Ta ni le dínà ohun tí mo bá níí ṣe?”

Sísá kúrò ní Babiloni

14 OLUWA, Ẹni Mímọ́ Israẹli, Olùràpadà yín, ní,

“N óo ranṣẹ sí Babiloni nítorí yín,

n óo dá gbogbo ọ̀pá ìlẹ̀kùn ibodè,

ariwo ẹ̀rín àwọn ará Kalidea yóo sì di ẹkún.

15 Èmi ni OLUWA, Ẹni Mímọ́ yín,

Ẹlẹ́dàá Israẹli, Ọba yín.”

16 OLUWA tí ó la ọ̀nà sí ojú òkun,

tí ó la ọ̀nà lórí agbami ńlá;

17 ẹni tí ó kó kẹ̀kẹ́ ogun ati ẹṣin jáde, ogun, ati àwọn ọmọ-ogun;

wọ́n dùbúlẹ̀ wọn kò lè dìde mọ́,

wọ́n kú bí iná fìtílà.

18 ÓLUWA ní, “Ẹ gbàgbé àwọn ohun àtijọ́,

kí ẹ sì mú ọkàn kúrò ninu ohun tí ó ti kọjá.

19 Ẹ wò ó! Mò ń ṣe nǹkan titun

ó ti yọ jáde nisinsinyii,

àbí ẹ kò ṣe akiyesi rẹ̀?

N óo la ọ̀nà ninu aginjù,

n óo sì mú kí omi máa ṣàn ninu aṣálẹ̀.

20 Àwọn ẹranko ìgbẹ́ yóo máa yìn mí lógo,

ati àwọn ọ̀fàfà ati ògòǹgò;

nítorí pé mo ti ṣe odò ńlá fún wọn ninu aṣálẹ̀,

kí àwọn àyànfẹ́ mi lè máa rí omi mu:

21 Àwọn tí mo fọwọ́ mi dá fún ara mi,

kí wọ́n lè kéde ògo mi.

Ẹ̀ṣẹ̀ Israẹli

22 “Sibẹsibẹ, ẹ kò ké pè mí, ẹ̀yin ọmọ Jakọbu,

ọ̀rọ̀ mi ti su yín, ẹ̀yin ọmọ Israẹli.

23 Ẹ kò wá fi aguntan rúbọ sí mi,

tabi kí ẹ wá fi ẹbọ rírú bu ọlá fún mi.

N kò fi tipátipá mu yín rúbọ,

bẹ́ẹ̀ ni n kò sọ pé dandan ni kí ẹ mú turari wá.

24 Ẹ kò fowó yín ra turari olóòórùn dídùn fún mi,

tabi kí ẹ fi ọ̀rá ẹbọ yín tẹ́ mi lọ́rùn.

Kàkà bẹ́ẹ̀ ẹ̀ ń fi ẹ̀ṣẹ̀ yín yọ mí lẹ́nu,

ẹ sì ń dààmú mi pẹlu àìdára yín.

25 Èmi, èmi ni mo pa ẹ̀ṣẹ̀ yín rẹ́,

nítorí ti ara mi;

n kò sì ní ranti àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín mọ́.

26 “Ẹ rán mi létí ọ̀rọ̀ yín kí á jọ ṣàríyànjiyàn;

ẹ ro ẹjọ́ tiyín,

kí á lè da yín láre.

27 Baba ńlá yín àkọ́kọ́ ṣẹ̀,

àwọn aṣiwaju yín náà sì ṣẹ̀ mí.

28 Nítorí náà mo sọ àwọn olórí ibi mímọ́ mi di aláìmọ́,

mo fi Jakọbu sílẹ̀ fún ìparun;

mo sì sọ Israẹli di ẹni ẹ̀sín.”

Categories
AISAYA

AISAYA 44

Ọlọrun kanṣoṣo ni OLUWA

1 OLUWA ní:

“Ṣugbọn nisinsinyii, ẹ̀yin ọmọ Jakọbu iranṣẹ mi

ẹ̀yin ọmọ Israẹli, àyànfẹ́ mi.

2 Ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA, Ẹlẹ́dàá yín wí,

ẹni tí ó ṣẹ̀dá yín láti inú oyún,

tí yóo sì ràn yín lọ́wọ́:

Ẹ má bẹ̀rù ẹ̀yin ọmọ Jakọbu, iranṣẹ mi,

Jeṣuruni, ẹni tí mo yàn.

3 “N óo tú omi sórí ilẹ̀ tí òùngbẹ ń gbẹ

n óo sì ṣe odò sórí ilẹ̀ gbígbẹ.

N óo tú ẹ̀mí mi sórí àwọn ọmọ yín,

n óo da ibukun mi sórí arọmọdọmọ yín,

4 wọn óo rúwé bíi koríko inú omi

àní, bíi igi wilo lẹ́bàá odò tí ń ṣàn.

5 “Ẹnìkan yóo wí pé,

‘OLUWA ló ni mí.’

Ẹnìkejì yóo pe ara rẹ̀ ní orúkọ Jakọbu.

Ẹlòmíràn yóo kọ ‘Ti OLUWA ni’ sí apá rẹ̀

yóo máa fi orúkọ Israẹli ṣe àpèjá orúkọ rẹ̀.”

6 Gbọ́ ohun tí OLUWA, ọba Israẹli ati Olùràpadà rẹ̀ wí,

OLUWA àwọn ọmọ ogun, ó ní,

“Èmi ni ẹni ìbẹ̀rẹ̀ ati ẹni òpin;

lẹ́yìn mi, kò sí Ọlọrun mìíràn.

7 Ta ni ó dàbí mi? Kí olúwarẹ̀ sọ̀rọ̀

kí ó kéde rẹ̀ níwájú mi.

Ẹni tí ó bá ti kéde láti ìbẹ̀rẹ̀, nípa àwọn nǹkan tí yóo ṣẹlẹ̀,

kí wọn sọ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ fún wa.

8 Má bẹ̀rù, má sì fòyà.

Ṣebí mo ti sọ fún ọ tipẹ́,

mo ti kéde rẹ̀,

ìwọ sì ni ẹlẹ́rìí mi:

Ǹjẹ́ Ọlọrun mìíràn wà lẹ́yìn mi?

Kò tún sí àpáta kan mọ́, n kò mọ ọ̀kan kan.”

A fi Ìwà Ìbọ̀rìṣà ṣẹ̀sín

9 Asán ni àwọn tí ń gbẹ́ ère, ohun tí inú wọn dùn sí kò lérè. Àwọn tí ń jẹ́rìí wọn kò ríran, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò mọ nǹkan, ojú ìbá le tì wọ́n.

10 Ta ló ṣe oriṣa, ta ló sì yá ère tí kò lérè?

11 Ojú yóo ti gbogbo wọn; eniyan sá ni wọ́n. Ẹ jẹ́ kí gbogbo wọn pésẹ̀, kí wọ́n jáde wá. Ìpayà yóo bá wọn, ojú yóo sì ti gbogbo wọn papọ̀.

12 Alágbẹ̀dẹ a mú irin, a fi sinu iná, a máa fi ọmọ owú lù ú, a sì fi agbára rẹ̀ rọ ọ́ bí ó ti fẹ́ kí ó rí. Ebi a pa á, àárẹ̀ a sì mú un; kò ní mu omi, a sì máa rẹ̀ ẹ́.

13 Agbẹ́gilére a ta okùn sára igi, a fi ẹfun fa ìlà sí i, a fi ìwọ̀n wọ̀n ọ́n, a sì gbẹ́ ẹ bí eniyan: ẹwà rẹ̀ a dàbí ti eniyan, wọn a sì kọ́lé fún un.

14 Ó lè gé igi kedari lulẹ̀, tabi kí ó gbin igi Sipirẹsi, tabi igi Oaku, kí ó jẹ́ kí ó dàgbà láàrin àwọn igi inú igbó. Ó sì lè gbin igi kedari kan, omi òjò a sì mú kí ó dàgbà.

15 Lẹ́yìn náà igi yìí di igi ìdáná: Eniyan óo gé ninu rẹ̀, yóo fi dáná yá; yóo gé ninu rẹ̀ yóo fi dáná oúnjẹ; yóo gé ninu rẹ̀, yóo fi gbẹ́ ère, yóo máa bọ ọ́. Eniyan á wá sọ igi lásán tí ó gbẹ́ di oriṣa, á sì máa foríbalẹ̀ fún un.

16 Yóo fi ìdajì rẹ̀ dáná, yóo fi se oúnjẹ, yóo fi se ẹran rẹ̀ pẹlu. Yóo jẹun, yóo jẹran, yóo yó; yóo tún yáná. Yóo ní, “Áà! Ooru mú mi nítorí mo rí iná yá.”

17 Yóo fi èyí tí ó kù gbẹ́ ère oriṣa rẹ̀, yóo máa foríbalẹ̀ fún un, yóo máa bọ ọ́, yóo máa gbadura sí i pé, “Gbà mí, nítorí ìwọ ni Ọlọrun mi.”

18 Wọn kò mọ nǹkan, bẹ́ẹ̀ ni òye kò yé wọn. Nǹkankan ti bò wọ́n lójú kí wọn má baà lè ríran; ó sì ti sé wọn lọ́kàn kí òye má baà yé wọn.

19 Kò sí ẹni tí ó ronú wò, tabi tí ó ní ìmọ̀ tabi òye, láti wí pé: “Ìdajì igi yìí ni mo fi dáná tí mo fi se oúnjẹ, tí mo sì fi se ẹran tí mo jẹ. Kí ló wá dé tí n óo ṣe fi ìyókù gbẹ́ ère kí n máa bọ ọ́? Ṣé ìtì igi lásán ló yẹ kí n máa foríbalẹ̀ fún, kí n máa bọ?”

20 Kò yàtọ̀ sí ẹni tí ń pe eérú ní oúnjẹ. Èrò ẹ̀tàn ti ṣì í lọ́nà, kò sì lè gba ara rẹ̀ kalẹ̀ tabi kí ó bi ara rẹ̀ pé, “Ǹjẹ́ irọ́ kọ́ ni ohun tí ó wà lọ́wọ́ mi yìí?”

OLUWA, Ẹlẹ́dàá ati Olùgbàlà

21 Jakọbu, ranti àwọn nǹkan wọnyi,

nítorí pé iranṣẹ mi ni ọ́, ìwọ Israẹli.

Èmi ni mo ṣẹ̀dá rẹ, iranṣẹ mi ni ọ́,

n kò jẹ́ gbàgbé rẹ, Israẹli.

22 Mo ti ká àìdára rẹ kúrò bí awọsanma,

mo ti gbá ẹ̀ṣẹ̀ rẹ dànù bí ìkùukùu.

Pada sọ́dọ̀ mi, nítorí mo ti rà ọ́ pada.

23 Ẹ hó ìhó ayọ̀, ẹ̀yin ọ̀run, nítorí OLUWA ti ṣe é.

Ẹ pariwo, ẹ̀yin ìsàlẹ̀ ilẹ̀.

Ẹ kọrin, ẹ̀yin òkè ńlá, ìwọ igbó ati igi inú rẹ̀,

nítorí OLUWA ti ra Jakọbu pada,

yóo sì ṣe ara rẹ̀ lógo ní Israẹli.

24 Gbọ́ ohun tí OLUWA, Olùràpadà rẹ wí,

ẹni tí ó ṣẹ̀dá rẹ láti inú oyún.

Ó ní, “Èmi ni OLUWA, tí mo dá ohun gbogbo.

Èmi nìkan ni mo tẹ́ ojú ọ̀run,

tí mo sì dá ilẹ̀ ayé tẹ́,

25 èmi tí mo sọ àmì àwọn tí ń woṣẹ́ èké di asán,

tí mo sì sọ àwọn aláfọ̀ṣẹ di òmùgọ̀.

Mo yí ọgbọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n po

mo sì sọ ọgbọ́n wọn di òmùgọ̀.

26 Èmi tí mo jẹ́rìí sí ọ̀rọ̀ iranṣẹ mi,

tí mo sì mú ìmọ̀ àwọn ikọ̀ mi ṣẹ,

èmi tí mo wí fún Jerusalẹmu pé,

‘Àwọn eniyan yóo máa gbé inú rẹ,’

tí mo sì wí fún àwọn ìlú Juda pé,

‘A óo tún odi yín mọ,

n óo sì tún yín kọ́.’

27 Èmi tí mo pàṣẹ fún agbami òkun pé, ‘Gbẹ!

n óo mú kí àwọn odò rẹ gbẹ;’

28 èmi tí mo sọ fún Kirusi pé:

‘Ìwọ ni ọba tí n óo yàn tí yóo mú gbogbo ìpinnu mi ṣẹ;’

tí mo sọ fún Jerusalẹmu pé:

‘A óo tún odi rẹ̀ mọ,’

tí mo sì sọ fún Tẹmpili pé,

‘A óo tún fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lélẹ̀.’ ”

Categories
AISAYA

AISAYA 45

OLUWA Yan Kirusi

1 Ohun tí OLUWA sọ fún kirusi, ẹni tí ó fi àmì òróró yàn nìyí:

Ẹni tí OLUWA di ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ mú, tí ó lò,

láti rẹ àwọn orílẹ̀-èdè sílẹ̀ níwájú rẹ̀,

láti tú àmùrè àwọn ọba,

láti ṣí àwọn ìlẹ̀kùn níwájú rẹ̀,

kí ẹnubodè má lè tì.

2 OLUWA ní, “N óo lọ ṣáájú rẹ,

n óo sọ àwọn òkè ńlá di pẹ̀tẹ́lẹ̀;

n óo fọ́ ìlẹ̀kùn idẹ,

n óo sì gé ọ̀pá ìlẹ̀kùn irin.

3 N óo fún ọ ní ìṣúra tí wọ́n fi pamọ́ sinu òkùnkùn,

ati àwọn nǹkan tí wọ́n kó pamọ́ síkọ̀kọ̀;

kí o lè mọ̀ pé èmi, OLUWA, Ọlọrun Israẹli,

ni mo pè ọ́ ní orúkọ rẹ.

4 Nítorí Jakọbu, iranṣẹ mi,

ati Israẹli, àyànfẹ́ mi,

mo pè ọ́ ní orúkọ rẹ.

Mo pe orúkọ rẹ ní àpèjá, bẹ́ẹ̀ ni o kò mọ̀ mí.

5 “Èmi ni OLUWA kò sí ẹlòmíràn,

kò sí Ọlọrun mìíràn lẹ́yìn mi.

Mo dì ọ́ ní àmùrè bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o kò mọ̀ mí.

6 Kí àwọn eniyan lè mọ̀ pé, láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ rẹ̀,

kò sí ẹlòmíràn lẹ́yìn mi.

Èmi ni OLUWA, kò tún sí ẹlòmíràn.

7 Èmi ni mo dá ìmọ́lẹ̀ ati òkùnkùn,

èmi ni mo dá alaafia ati àjálù:

Èmi ni OLUWA tí mo ṣe gbogbo nǹkan wọnyi.

8 Rọ òjò sílẹ̀, ìwọ ọ̀run,

kí ojú ọ̀run rọ̀jò òdodo sílẹ̀.

Jẹ́ kí ilẹ̀ lanu, kí ìgbàlà lè yọ jáde.

Jẹ́ kí ó mú kí òdodo yọ jáde pẹlu,

èmi OLUWA ni mo ṣẹ̀dá rẹ̀ bẹ́ẹ̀.

OLUWA Ẹlẹ́dàá Ayé ati Ìtàn

9 “Ẹni tí ń bá ẹlẹ́dàá rẹ̀ jà gbé!

Ìkòkò tí ń bá amọ̀kòkò jà.

Ṣé amọ̀ lè bèèrè lọ́wọ́ ẹni tí ń mọ ọ́n pé:

‘Kí ni ò ń mọ?’

Tabi kí ó sọ fún un pé,

‘Nǹkan tí ò ń mọ kò ní ìgbámú?’

10 Ẹnìkan lè bi baba rẹ̀ pé:

‘Irú kí ni o bí?’

Tabi kí ó bi ìyá rẹ̀ léèrè pé:

‘Irú ọmọ wo ni o bí yìí?’

Olúwarẹ̀ gbé!”

11 OLUWA, Ẹni Mímọ́ Israẹli, ẹlẹ́dàá rẹ ni,

“Ṣé ẹ óo máa bi mí ní ìbéèrè nípa àwọn ọmọ mi ni,

tabi ẹ óo máa pàṣẹ fún mi nípa iṣẹ́ ọwọ́ mi?

12 Èmi ni mo dá ayé,

tí mo dá eniyan sórí rẹ̀.

Ọwọ́ mi ni mo fi ta ojú ọ̀run bí aṣọ,

tí mo sì pàṣẹ fún oòrùn, òṣùpá ati àwọn ìràwọ̀.

13 Èmi ni mo gbé Kirusi dìde ninu òdodo mi,

n óo mú kí ó ṣe nǹkan bí ó ti tọ́;

òun ni yóo tún ìlú mi kọ́,

yóo sì dá àwọn eniyan mi tí wọ́n wà ní ìgbèkùn sílẹ̀,

láìgba owó ati láìwá èrè kan.”

OLUWA àwọn ọmọ ogun ló sọ bẹ́ẹ̀.

14 Ó ní, “Àwọn ọrọ̀ ilẹ̀ Ijipti ati àwọn ẹrù ilẹ̀ Etiopia,

ati àwọn ọkunrin Seba tí wọn ṣígbọnlẹ̀,

wọn óo tọ̀ ọ́ wá, wọn óo di tìrẹ,

wọn óo sì máa tẹ̀lé ọ.

Wọn óo wá, pẹlu ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ lẹ́sẹ̀ wọn,

wọn óo sì wólẹ̀ fún ọ.

Wọn óo máa bẹ̀ ọ́ pé,

‘Lọ́dọ̀ rẹ nìkan ni Ọlọrun wà,

kò tún sí Ọlọrun mìíràn.

Kò sí Ọlọrun mìíràn lẹ́yìn rẹ.’ ”

15 Nítòótọ́,

ìwọ ni Ọlọrun tí ó ń fi ara pamọ́,

Ọlọrun Israẹli, Olùgbàlà.

16 Gbogbo àwọn oriṣa ni a óo dójú tì,

ìdààmú yóo sì bá wọn.

Gbogbo àwọn tí ń gbẹ́ ère

yóo bọ́ sinu ìdààmú papọ̀.

17 Ṣugbọn OLUWA gba Israẹli là,

títí ayé sì ni ìgbàlà rẹ̀.

Ojú kò ní tì ọ́, bẹ́ẹ̀ ni o kò ní dààmú, títí lae.

18 Ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA wí,

OLUWA tí ó dá ọ̀run. (Òun ni Ọlọrun.)

Òun ni ó dá ilẹ̀, tí ó fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀,

kò dá a ninu rúdurùdu,

ṣugbọn ó dá a kí eniyan lè máa gbé inú rẹ̀

Ó ní, “Èmi ni OLUWA, kò sí Ọlọrun mìíràn.

19 N kò sọ ọ́ níkọ̀kọ̀, ninu òkùnkùn.

N kò sọ fún arọmọdọmọ Jakọbu pé:

‘Ẹ máa wá mi ninu rúdurùdu.’

Òtítọ́ ni Èmi OLUWA sọ.

Ohun tí ó tọ́ ni mò ń kéde.”

OLUWA Gbogbo Ayé ati Àwọn Oriṣa Babiloni

20 OLUWA ní:

“Ẹ kó ara yín jọ kí ẹ wá,

ẹ jọ súnmọ́ bí,

gbogbo ẹ̀yin tí ẹ kù ninu àwọn orílẹ̀-èdè.

Aláìlóye ni àwọn tí ń gbẹ́ ère igi lásán kiri,

tí wọ́n sì ń gbadura

sí oriṣa tí kò lè gbànìyàn là.

21 Ẹ sọ̀rọ̀ jáde, kí ẹ sì ro ẹjọ́ tiyín,

jẹ́ kí wọ́n jọ gbìmọ̀ pọ̀.

Ta ló sọ èyí láti ìgbà laelae?

Ta ló kéde rẹ̀ láti ìgbà àtijọ́?

Ṣebí èmi OLUWA ni?

Kò tún sí Ọlọrun mìíràn lẹ́yìn mi.

Ọlọrun Olódodo ati Olùgbàlà

kò tún sí ẹnìkan mọ́, àfi èmi.

22 “Ẹ yipada sí mi kí á gbà yín là,

gbogbo ẹ̀yin òpin ayé.

Nítorí èmi ni Ọlọrun,

kò tún sí ẹlòmíràn mọ́.

23 Mo ti fi ara mi búra,

mo sì fi ẹnu mi sọ̀rọ̀ pẹlu òtítọ́ inú,

ọ̀rọ̀ tí kò ní yipada:

‘Gbogbo orúnkún ni yóo wólẹ̀ fún mi,

èmi ni gbogbo eniyan yóo sì búra pé àwọn óo máa sìn.’

24 “Nípa èmi nìkan ni àwọn eniyan yóo máa pé,

‘Ninu OLUWA ni òdodo ati agbára wà.’

Gbogbo àwọn tí ń bá a bínú

yóo pada wá sọ́dọ̀ rẹ̀ pẹlu ìtìjú.

25 Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli yóo ṣẹgun,

wọn yóo sì ṣògo ninu OLUWA.

Categories
AISAYA

AISAYA 46

1 “Oriṣa Bẹli tẹríba, oriṣa Nebo doríkodò.

Orí àwọn ẹran ọ̀sìn ati mààlúù ni àwọn oriṣa wọn wà.

Àwọn nǹkan tí ẹ̀ ń rù kiri wá di ẹrù, tí àwọn ẹranko tí ó ti rẹ̀ ń rù.

2 Àwọn mejeeji jọ tẹríba, wọ́n jọ doríkodò,

wọn ò lè gba àwọn ẹrù wọn kalẹ̀.

Àwọn pàápàá yóo lọ sí ìgbèkùn.

3 “Ẹ tẹ́tí sí mi, ẹ̀yin ará ilé Jakọbu,

ati gbogbo ará ilé Israẹli tí ó ṣẹ́kù;

ẹ̀yin tí mo pọ̀n láti ọjọ́ tí wọ́n ti bi yín,

tí mo sì gbé láti inú oyún.

4 Èmi náà ni, títí di ọjọ́ ogbó yín,

n óo gbé yín títí tí ẹ óo fi hewú lórí.

Èmi ni mo da yín, n óo sì máa tọ́jú yín,

n óo máa gbé yín, n óo sì gbà yín là.

5 “Ta ni ẹ óo fi mí wé?

Ta ni ẹ óo fi díwọ̀n mi?

Ta ni ẹ lè fi wé mi, kí á lè jọ jẹ́ bákan náà?

6 Àwọn kan ń kó ọpọlọpọ wúrà jáde ninu àpò,

wọ́n sì ń wọn fadaka lórí ìwọ̀n.

Wọ́n sanwó ọ̀yà fún alágbẹ̀dẹ wúrà, ó bá wọn fi dá oriṣa.

Wọ́n wá ń foríbalẹ̀ fún un, wọ́n ń sìn ín.

7 Wọn á gbé e lé èjìká wọn,

wọn á gbé e sípò rẹ̀, á sì dúró kabẹ̀.

Kò ní le kúrò níbẹ̀ lọ sí ibìkankan.

Bí eniyan bá ké pè é, kò lè gbọ́,

kò lè yọ eniyan ninu ìṣòro rẹ̀.

8 “Ẹ ranti èyí, kí ẹ dà á rò,

ẹ fi ọkàn rò ó, ẹ̀yin ẹlẹ́ṣẹ̀.

9 Ẹ ranti àwọn nǹkan ti àtijọ́,

nítorí pé èmi ni Ọlọrun, kò sí Ọlọrun mìíràn mọ́.

Èmi ni Ọlọrun, kò sí ẹni tí ó dà bí mi.

10 Láti ìbẹ̀rẹ̀ ni èmi tíí sọ ohun tí ó gbẹ̀yìn.

Láti ìgbà àtijọ́,

ni mo tí ń sọ àwọn nǹkan tí kò ì tíì ṣẹlẹ̀.

Èmi a máa sọ pé: ‘Àbá mi yóo ṣẹ,

n óo sì mú ìpinnu mi ṣẹ.’

11 Mo pe idì láti ìlà oòrùn,

mo sì ti pe ẹni tí yóo mú àbá mi ṣẹ láti ilẹ̀ òkèèrè wá.

Mo ti sọ̀rọ̀, n óo sì mú un ṣẹ,

mo ti ṣe ìpinnu, n óo sì ṣe é.

12 “Ẹ fetí sí mi, ẹ̀yin aláìgbọràn, ẹ̀yin tí ẹ jìnnà sí ìgbàlà.

13 Mo mú ìdáǹdè mi wá sí tòsí, kò jìnnà mọ́,

ìgbàlà mi kò ní pẹ́ dé.

N óo fi ìgbàlà mi sí Sioni, fún Israẹli, ògo mi.”

Categories
AISAYA

AISAYA 47

Ìdájọ́ lórí Babiloni

1 Sọ̀kalẹ̀ kí o jókòó ninu eruku, ìwọ Babiloni.

Jókòó ní ilẹ̀ẹ́lẹ̀, láìsí ìtẹ́-ọba,

ìwọ ọmọbinrin Kalidea.

A kò ní pè ọ́ ní ẹlẹgẹ́ ati aláfẹ́ mọ́.

2 Gbé ọlọ kí o máa lọ ọkà,

ṣí aṣọ ìbòjú rẹ kúrò,

ká aṣọ rẹ sókè, kí o ṣí ẹsẹ̀ rẹ sílẹ̀,

kí o sì la odò kọjá.

3 A óo tú ọ sí ìhòòhò,

a óo sì rí ìtìjú rẹ.

N óo gbẹ̀san,

n kò sì ní dá ẹnìkan kan sí.

4 Olùràpadà wa, tí ń jẹ́ OLUWA àwọn ọmọ ogun, ni Ẹni Mímọ́ Israẹli.

5 OLUWA wí nípa Kalidea pé:

“Jókòó kí o dákẹ́ jẹ́ẹ́, kí o sì wọ inú òkùnkùn lọ,

ìwọ ọmọbinrin Kalidea.

Nítorí a kò ní pè ọ́ ní ayaba àwọn orílẹ̀-èdè mọ́.

6 Inú bí mi sí àwọn eniyan mi,

mo sì sọ nǹkan ìní mi di ohun ìríra.

Mo fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́,

o kò ṣàánú wọn.

O di àjàgà wúwo rẹ mọ́ àwọn arúgbó lọ́rùn.

7 O sọ pé ìwọ ni o óo máa jẹ́ ayaba títí lae,

nítorí náà o kò kó àwọn nǹkan wọnyi lékàn,

o kò sì ranti ìgbẹ̀yìn wọn.

8 “Nítorí náà, gbọ́ nisinsinyii, ìwọ tí o fẹ́ràn afẹ́ ayé,

tí o jókòó láìléwu,

tí ò ń sọ lọ́kàn rẹ pé,

‘Èmi nìkan ni mo wà,

kò sí ẹlòmíràn lẹ́yìn mi.

N kò ní di opó,

bẹ́ẹ̀ ni n kò ní ṣòfò ọmọ.’

9 Ọ̀fọ̀ mejeeji ni yóo ṣe ọ́ lójijì,

lọ́jọ́ kan náà: o óo ṣòfò ọmọ, o óo sì di opó,

ibi yìí yóo dé bá ọ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́.

Ò báà lóṣó, kí o lájẹ̀ẹ́,

kí àfọ̀ṣẹ rẹ sì múná jù bẹ́ẹ̀ lọ.

10 “Ọkàn rẹ balẹ̀ ninu iṣẹ́ ibi rẹ,

o ní ẹnìkan kò rí ọ.

Ọgbọ́n ati ìmọ̀ rẹ mú ọ ṣìnà,

ò ń sọ ní ọkàn rẹ pé, ‘Èmi nìkan ní mo wà.

Kò sí ẹlòmíràn lẹ́yìn mi.’

11 Ṣugbọn ibi yóo dé bá ọ,

tí o kò ní lè dáwọ́ rẹ̀ dúró;

àjálù yóo dé bá ọ,

tí o kò ní lè ṣe ètùtù rẹ̀;

ìparun yóo dé bá ọ lójijì,

tí o kò ní mọ nǹkankan nípa rẹ̀.

12 Múra sí àfọ̀ṣẹ rẹ,

sì múra si oṣó ṣíṣẹ́ jọ,

tí o ti dáwọ́ lé láti kékeré,

bóyá o óo tilẹ̀ yege,

tabi bóyá o sì lè dẹ́rùba eniyan.

13 Ọpọlọpọ ìmọ̀ràn tí wọn fún ọ ti sú ọ;

jẹ́ kí wọn dìde nílẹ̀ kí wọ́n gbà ọ́ wàyí,

àwọn tí ó ń wojú ọ̀run,

ati àwọn awòràwọ̀;

tí wọn ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ sí ọ,

nígbà tí oṣù bá ti lé.

14 “Wò ó! Wọ́n dàbí àgékù koríko,

iná ni yóo jó wọn ráúráú,

wọn kò sì ní lè gba ara wọn kalẹ̀, ninu ọ̀wọ́ iná.

Eléyìí kì í ṣe iná tí eniyan ń yá,

kì í ṣe iná tí eniyan lè jókòó níwájú rẹ̀.

15 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn tí ẹ jọ ń ṣiṣẹ́ pọ̀ rí sí ọ,

àwọn tí ẹ ti jọ ń ṣòwò pọ̀ láti ìgbà èwe rẹ.

Olukuluku wọn ti ṣìnà lọ,

kò sí ẹni tí yóo gbà ọ́ sílẹ̀.”

Categories
AISAYA

AISAYA 48

Ọlọrun ni OLUWA Ọjọ́ Iwájú

1 Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ẹ̀yin ará ilé Jakọbu,

ẹ̀yin tí à ń fi orúkọ Israẹli pè,

ọmọ bíbí inú Juda,

ẹ̀yin tí ẹ̀ ń forúkọ OLUWA búra,

tí ẹ jẹ́wọ́ Ọlọrun Israẹli,

ṣugbọn tí kì í ṣe pẹlu òdodo tabi òtítọ́.

2 Ẹ̀ ń pe ara yín ní ará ìlú mímọ́,

ẹ fẹ̀yìn ti Ọlọrun Israẹli,

tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ OLUWA àwọn ọmọ ogun.

3 OLUWA ní, “Láti ìgbà àtijọ́ ni mo ti kéde,

àwọn nǹkan tí yóo ṣẹlẹ̀,

èmi ni mo sọ wọ́n jáde,

tí mo sì fi wọ́n hàn.

Lójijì mo ṣe wọ́n,

nǹkan tí mo sọ sì ṣẹ.

4 Nítorí mo mọ̀ pé alágídí ni yín,

olóríkunkun sì ni yín pẹlu.

5 Mo ti sọ fun yín láti ọjọ́ pípẹ́:

kí wọn tó ṣẹlẹ̀, mo ti kéde wọn fun yín,

kí ẹ má baà sọ pé, ‘oriṣa wa ni ó ṣe wọ́n,

àwọn ère wa ni ó pàṣẹ pé kí wọn ṣẹlẹ̀.’

6 “Ẹ ti fetí ara yín gbọ́,

nítorí náà, ẹ wo gbogbo èyí, ṣé ẹ kò ní kéde rẹ̀?

Láti àkókò yìí lọ, n óo mú kí ẹ máa gbọ́ nǹkan tuntun,

àwọn nǹkan tí ó farapamọ́ tí ẹ kò mọ̀.

7 Kò tíì pẹ́ tí a dá wọn,

ẹ kò gbọ́ nípa wọn rí, àfi òní.

Kí ẹ má baà wí pé:

Wò ó, a mọ̀ wọ́n.

8 Ẹ kò gbọ́ ọ rí,

bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò mọ̀ ọ́n tẹ́lẹ̀.

Ọjọ́ ti pẹ́ tí a ti di yín létí,

nítorí mo mọ̀ pé ẹ óo hùwà àgàbàgebè,

ọlọ̀tẹ̀ ni orúkọ tí mo mọ̀ yín mọ̀,

láti ìgbà tí ẹ ti jáde ninu oyún.

9 “Mo dáwọ́ ibinu mi dúró ná, nítorí orúkọ mi,

nítorí ìyìn mi ni mo ṣe dá a dúró fun yín,

kí n má baà pa yín run.

10 Mo ti fọ̀ ọ́ mọ́,

ṣugbọn kì í ṣe bí a tií fọ fadaka,

mo dán yín wò ninu iná ìpọ́njú.

11 Nítorí tèmi, àní nítorí tèmi ni mo ṣe ṣe bẹ́ẹ̀.

Nítorí kí ni ìdí rẹ̀ tí orúkọ mi yóo ṣe díbàjẹ́,

n kò ní gbé ògo mi fún ẹlòmíràn.

Kirusi Alákòóso tí OLUWA Yàn

12 “Tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ mi ìwọ Jakọbu,

ìwọ Israẹli, ẹni tí mo pè,

Èmi ni ẹni ìbẹ̀rẹ̀,

èmi sì ni ẹni òpin.

13 Ọwọ́ mi ni mo fi fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀,

ọwọ́ ọ̀tún mi ni mo fi ta awọsanma sójú ọ̀run.

Nígbà tí mo pè wọ́n, gbogbo wọn jọ yọ síta.

14 “Gbogbo yín, ẹ péjọ, kí ẹ gbọ́,

èwo ninu wọn ni ó kéde nǹkan wọnyi?

OLUWA fẹ́ràn rẹ̀,

yóo mú ìfẹ́ inú rẹ̀ ṣẹ lórí Babiloni,

yóo sì gbógun ti àwọn ará Kalidea.

15 Èmi, àní èmi pàápàá ni mo sọ̀rọ̀, tí mo pè é,

èmi ni mo mú un wá,

yóo sì ṣe àṣeyege ninu àdáwọ́lé rẹ̀.

16 Ẹ súnmọ́ mi, kí ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí,

láti ìbẹ̀rẹ̀ wá, n kò sọ̀rọ̀ ní àṣírí,

láti ìgbà tí ọ̀rọ̀ náà ti ṣe ni mo ti wà níbẹ̀.”

Nisinsinyii, OLUWA, Ọlọrun, ati Ẹ̀mí rẹ̀ ti rán mi.

Ìlànà Ọlọrun fún Àwọn Eniyan Rẹ̀

17 OLUWA, Olùràpadà rẹ, Ẹni Mímọ́ Israẹli, ní,

“Èmi ni OLUWA Ọlọrun rẹ,

tí ń kọ́ ọ ní ohun tí yóo ṣe ọ́ ní anfaani,

tí ń darí rẹ, sí ọ̀nà tí ó yẹ kí o gbà.

18 “Ìbá jẹ́ pé o ti fetí sí òfin mi,

alaafia rẹ ìbá máa ṣàn bí odò,

òdodo rẹ ìbá lágbára bi ìgbì omi òkun.

19 Àwọn ọmọ rẹ ìbá pọ̀ bí iyanrìn,

arọmọdọmọ rẹ ìbá pọ̀ bí erùpẹ̀ ilẹ̀ tí kò lóǹkà.

Orúkọ wọn kì bá tí parẹ́ títí ayé,

bẹ́ẹ̀ ni kì bá tí parun lae níwájú mi.”

20 Ẹ jáde kúrò ní Babiloni,

ẹ sá kúrò ní Kalidea,

ẹ sọ ọ́ pẹlu ayọ̀,

ẹ kéde rẹ̀,

ẹ máa ròyìn rẹ̀ lọ títí dè òpin ayé, pé

“OLUWA ti ra Jakọbu iranṣẹ rẹ̀ pada.”

21 Òùngbẹ kò gbẹ wọ́n,

nígbà tí ó mú wọn la inú aṣálẹ̀ kọjá,

ó tú omi jáde fún wọn láti inú àpáta,

ó la àpáta, omi sì tú jáde.

22 OLUWA sọ pé, “Kò sí alaafia fún àwọn eniyan burúkú.”

Categories
AISAYA

AISAYA 49

Israẹli, Ìmọ́lẹ̀ fún Ayé

1 Ẹ gbọ́, ẹ̀yin ilẹ̀ etí òkun.

Ẹ fetí sílẹ̀ sí ọ̀rọ̀ mi, ẹ̀yin ará ilẹ̀ òkèèrè,

láti inú oyún ni OLUWA ti pè mí,

láti inú ìyá mi wá ni ó ti dárúkọ mi.

2 Ó ṣe ẹnu mi bí idà mímú,

ó fi mí pamọ́ sí ibi òjìji ọwọ́ rẹ̀,

ó ṣe mí ní ọfà tí ó mú,

ó fi mí pamọ́ sinu apó rẹ̀.

3 Ó sọ fún mi pé, “Iranṣẹ mi ni ọ́, ìwọ Israẹli,

àwọn eniyan óo máa yìn mí lógo nítorí rẹ.”

4 Ṣugbọn mo dáhùn pé,

“Mo ti ṣiṣẹ́ àṣedànù.

Mo ti lo agbára mi ṣòfò, mo ti fi ṣe àṣedànù,

sibẹsibẹ ẹ̀tọ́ mi ń bẹ lọ́dọ̀ OLUWA.”

Ẹ̀san mi ń bẹ lọ́dọ̀ Ọlọrun mi, yóo san án fún mi.

5 Nisinsinyii, OLUWA, tí ó ṣẹ̀dá mi ninu oyún,

kí n lè jẹ́ iranṣẹ rẹ̀, láti mú Jakọbu pada tọ̀ ọ́ wá,

ati láti mú kí Israẹli kórajọ pọ̀ sọ́dọ̀ rẹ̀; nítorí mo níyì lójú OLUWA,

Ọlọrun mi sì ti di agbára mi.

6 OLUWA ní nǹkan kékeré ni kí n jẹ́ iranṣẹ òun,

láti gbé àwọn ẹ̀yà Jakọbu dìde, ati láti kó àwọn ọmọ Israẹli tí ó kù jọ.

Ó ní òun óo fi mí ṣe ìmọ́lẹ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè

kí ìgbàlà òun lè dé òpin ayé.

7 Ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA, Olùràpadà Israẹli, ati Ẹni Mímọ́ rẹ̀, sọ,

fún ẹni tí ayé ń gàn,

tí àwọn orílẹ̀-èdè kórìíra,

iranṣẹ àwọn aláṣẹ,

ó ní, “Àwọn ọba yóo rí ọ, wọn óo dìde,

àwọn ìjòyè yóo rí ọ, wọn óo sì dọ̀bálẹ̀.

Nítorí OLUWA, tí ó jẹ́ olódodo,

Ẹni Mímọ́ Israẹli, tí ó ti yàn ọ́.”

Ìmúpadàbọ̀sípò Jerusalẹmu

8 OLUWA ní,

“Ní àkókò ìtẹ́wọ́gbà mo dá ọ lóhùn,

lọ́jọ́ ìgbàlà, mo ràn ọ́ lọ́wọ́.

Mo ti pa ọ́ mọ́,

mo sì ti fi ọ́ dá majẹmu pẹlu àwọn aráyé,

láti fìdí ilẹ̀ náà múlẹ̀,

láti pín ilẹ̀ tí ó ti di ahoro.

9 Kí o máa sọ fún àwọn ẹlẹ́wọ̀n pé, ‘Ẹ jáde,’

ati fún àwọn tí ó wà ninu òkùnkùn pé, ‘Ẹ farahàn.’

Wọn óo rí ohun jíjẹ ní gbogbo ọ̀nà,

gbogbo orí òkè yóo sì jẹ́ ibùjẹ fún wọn.

10 Ebi kò ní pa wọ́n,

òùngbẹ kò sì ní gbẹ wọ́n,

atẹ́gùn gbígbóná kò ní fẹ́ lù wọ́n,

bẹ́ẹ̀ ni oòrùn kò ní pa wọ́n,

nítorí ẹni tí ó ṣàánú wọn ni yóo máa darí wọn,

yóo sì mú wọn gba ẹ̀gbẹ́ omi tí ń ṣàn.

11 “N óo sọ gbogbo òkè mi di ojú ọ̀nà,

n óo kún gbogbo òpópó ọ̀nà mi.

12 Wò ó! Òkèèrè ni èyí yóo ti wá,

láti àríwá ati láti ìwọ̀ oòrùn, àní láti ilẹ̀ Sinimu.”

13 Kí ọ̀run kọrin ayọ̀, kí ayé kún fún ayọ̀,

ẹ̀yin òkè, ẹ máa kọrin,

nítorí, OLUWA ti tu àwọn eniyan rẹ̀ ninu,

yóo ṣàánú àwọn eniyan rẹ̀ tí ìyà ń jẹ.

14 Sioni ń wí pé,

“OLUWA ti kọ̀ mí sílẹ̀,

Oluwa mi ti gbàgbé mi.”

15 OLUWA dáhùn pé, “Ǹjẹ́ abiyamọ le gbàgbé ọmọ tí ń fún lọ́mú?

Ṣé ó le má ṣàánú ọmọ bíbí inú rẹ̀?

Bí àwọn wọnyi tilẹ̀ gbàgbé.

Èmi kò ní gbàgbé rẹ.

16 Wò ó! Mo ti fi gègé fín orúkọ rẹ sí àtẹ́lẹwọ́ mi,

àwọn odi rẹ sì ńbẹ níwájú mi nígbà gbogbo.

17 “Àwọn ọmọ rẹ tí ń pada bọ̀ kíákíá,

àwọn olùparun rẹ yóo jáde kúrò ninu rẹ.

18 Gbójú sókè, kí o wò yíká,

gbogbo àwọn ọmọ rẹ péjọ, wọ́n tọ̀ ọ́ wá.

OLUWA fi ara rẹ̀ búra pé,

o óo gbé wọn wọ̀ bí nǹkan ọ̀ṣọ́ ara.

O óo wọ̀ wọ́n bí ìgbà tí iyawo kó ohun ọ̀ṣọ́ wọ̀.

19 “Dájúdájú ilẹ̀ rẹ tí ó ti di aṣálẹ̀,

ati àwọn tí ó ti di ahoro,

yóo kéré fún àwọn tí yóo máa gbé inú rẹ̀ tí ó bá yá,

a óo sì lé àwọn tí ó pa ọ́ run jìnnà sí ọ.

20 Àwọn ọmọ tí o bí ní àkókò ìgbèkùn rẹ

yóo sọ ní etígbọ̀ọ́ rẹ pé,

‘Ibí yìí kéré jù fún wa,

fún wa ní àyè sí i láti máa gbé.’

21 O óo bèèrè lọ́kàn ara rẹ nígbà náà pé,

‘Ta ni ó bí àwọn ọmọ wọnyi fún mi?

Ṣebí àwọn ọmọ mi ti kú, mo ti yàgàn,

mo sì lọ sí ìgbèkùn lóko ẹrú.

Ta ni ó wá tọ́ àwọn wọnyi dàgbà?

Ṣebí èmi nìkan ni mo ṣẹ́kù,

níbo ni àwọn wọnyi ti wá?’ ”

22 OLUWA Ọlọrun ní,

“Wò ó, n óo gbé ọwọ́ mi sókè sí àwọn orílẹ̀-èdè.

N óo gbé àsíá mi sókè sí àwọn eniyan,

wọn óo gbé àwọn ọmọ rẹ ọkunrin mọ́ àyà wọn

wọn óo sì gbé àwọn ọmọ rẹ obinrin sí èjìká.

23 Àwọn ọba ni yóo máa tọ́jú rẹ bíi baba,

àwọn ayaba yóo sì máa tọ́jú rẹ bí ìyá,

ní ìdojúbolẹ̀ ni wọn óo máa tẹríba fún ọ,

wọn óo sì máa pọ́n eruku ẹsẹ̀ rẹ lá.

O óo wá mọ̀ nígbà náà pé èmi ni OLUWA,

ojú kò ní ti àwọn tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé mi.”

24 Ǹjẹ́ a lè gba ìkógun lọ́wọ́ alágbára,

tabi kí á gba òǹdè lọ́wọ́ òkúrorò eniyan?

25 OLUWA ní:

“Bí ó bá tilẹ̀ ṣeéṣe láti gba òǹdè lọ́wọ́ alágbára,

tabi láti gba ìkógun lọ́wọ́ òkúrorò eniyan.

N óo bá àwọn tí ó ń bá ọ jà jà,

n óo sì gba àwọn ọmọ rẹ là.

26 N óo mú kí àwọn tó ń ni ọ́ lára máa pa ara wọn jẹ:

wọn óo máa mu ẹ̀jẹ̀ ara wọn, bí ẹni mu ọtí,

gbogbo ayé yóo sì mọ̀ nígbà náà pé,

èmi ni OLUWA, Olùgbàlà rẹ,

Olùràpadà rẹ, Ọlọrun alágbára Jakọbu.”