Categories
AISAYA

AISAYA 30

Àdéhùn tí kò Wúlò pẹlu Ijipti

1 OLUWA ní:

“Àwọn ọmọ aláìgbọràn gbé.

Àwọn tí wọn ń dá àbá tí ó yàtọ̀ sí tèmi,

tí wọn ń kó ẹgbẹ́ jọ,

ṣugbọn tí kìí ṣe nípa ẹ̀mí mi;

kí wọ́n lè máa dá ẹ̀ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀.

2 Wọ́n múra, wọ́n gbọ̀nà Ijipti

láì bèèrè ìmọ̀ràn lọ́dọ̀ mi.

Wọ́n lọ sápamọ́ sí abẹ́ ààbò Farao,

wọ́n lọ wá ààbò ní Ijipti.

3 Nítorí náà, ààbò Farao yóo di ìtìjú fún wọn,

ibi ìpamọ́ abẹ́ Ijipti yóo di ìrẹ̀sílẹ̀ fún wọn.

4 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn olórí wọn ti lọ sí Soani,

tí àwọn ikọ̀ wọn sì ti dé Hanesi.

5 Ojú yóo tì wọ́n, nítorí wọn ń wá ìrànlọ́wọ́ lọ sọ́dọ̀ àwọn tí kò lè ràn wọ́n lọ́wọ́.

Wọn kò lè rí ìrànwọ́ tabi anfaani kankan níbẹ̀, bíkòṣe ìtìjú ati ẹ̀gàn.”

Àsọtẹ́lẹ̀ nípa Àwọn ẹranko Ilẹ̀ Nẹgẹbu

6 Àsọtẹ́lẹ̀ nípa àwọn ẹranko ilẹ̀ Nẹgẹbu nìyí:

“Wọ́n di àwọn nǹkan ìní wọn sí ẹ̀yìn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́,

wọ́n sì di ìṣúra wọn sí ẹ̀yìn ràkúnmí.

Wọ́n ń la ilẹ̀ ìṣòro ati wahala kọjá.

Ilẹ̀ àwọn akọ kinniun ati abo kinniun,

ilẹ̀ paramọ́lẹ̀ ati ejò amúbíiná tí ń fò.

Wọ́n ń lọ sọ́dọ̀ àwọn eniyan tí kò lè ṣe wọ́n ní anfaani.

7 Nítorí ìmúlẹ̀mófo ni ìrànwọ́ Ijipti.

Nítorí náà ni mo ṣe pè é ní,

‘Rahabu tí ń jókòó lásán.’ ”

Àwọn Aláìgbọràn

8 Nisinsinyii lọ kọ ọ́ sílẹ̀ níwájú wọn,

kí o sì kọ ọ́ sinu ìwé,

kí ó lè wà títí di ẹ̀yìn ọ̀la,

gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí títí lae;

9 nítorí aláìgbọràn eniyan ni wọ́n,

Òpùrọ́ ọmọ tí kìí fẹ́ gbọ́ ìtọ́ni OLUWA.

10 Wọ́n á máa sọ fún àwọn aríran pé,

“Ẹ má ríran mọ.”

Wọ́n á sì máa sọ fún àwọn wolii pé,

“Ẹ má sọ àsọtẹ́lẹ̀ òtítọ́ fún wa mọ́,

ọ̀rọ̀ dídùn ni kí ẹ máa sọ fún wa,

kí ẹ sì máa sọ àsọtẹ́lẹ̀ ẹ̀tàn fún wa.

11 Ẹ fi ojú ọ̀nà sílẹ̀, ẹ yà kúrò lójú ọ̀nà,

ẹ má sọ nípa Ẹni Mímọ́ Israẹli fún wa mọ́.”

12 Nítorí náà, Ẹni Mímọ́ Israẹli ní:

“Nítorí pé ẹ kẹ́gàn ọ̀rọ̀ yìí,

ẹ gbẹ́kẹ̀lé ìninilára ati ẹ̀tàn,

ẹ sì gbára lé wọn,

13 nítorí náà, ẹ̀ṣẹ̀ tí ẹ̀ ń dá yìí;

yóo dàbí ògiri gíga tí ó là, tí ó sì fẹ́ wó;

lójijì ni yóo wó lulẹ̀ lẹ́ẹ̀kanṣoṣo.

14 Wíwó rẹ̀ yóo dàbí ìgbà tí eniyan la ìkòkò mọ́lẹ̀,

tí ó fọ́ yángá-yángá,

tóbẹ́ẹ̀ tí eniyan kò rí àpáàdì kan mú jáde ninu rẹ̀,

tí a lè fi fọn iná ninu ààrò,

tabi èkúfọ́, tí a lè fi bu omi ninu odò.”

15 Nítorí OLUWA Ọlọrun, Ẹni Mímọ́ Israẹli ní:

“Bí ẹ bá yipada, tí ẹ sì farabalẹ̀,

ẹ óo rí ìgbàlà;

bí ẹ bá dákẹ́ jẹ́ẹ́ tí ẹ sì gbẹ́kẹ̀lé Ọlọrun,

ẹ óo lágbára.

Ṣugbọn ẹ kọ̀.

16 Ẹ sọ pé ó tì o, ẹ̀yin óo gun ẹṣin sálọ ni.

Nítorí náà sísá ni ẹ óo sálọ.

Ẹ sọ pé ẹṣin tí ó lè sáré ni ẹ óo gùn.

Nítorí náà àwọn tí yóo máa le yín,

wọn óo lè sáré gan-an ni.

17 Ẹgbẹrun ninu yín yóo sá fún ẹyọ ọ̀tá yín kan,

gbogbo yín yóo sì sá fún ẹyọ eniyan marun-un

títí tí àwọn tí yóo kú ninu yín yóo fi dàbí igi àsíá lórí òkè.

Wọn óo dàbí àsíá ati àmì lórí òkè.”

18 Nítorí náà OLUWA ń dúró dè yín,

ó ti ṣetán láti ṣàánú yín.

Yóo dìde, yóo sì ràn yín lọ́wọ́.

Nítorí Ọlọrun Olódodo ni OLUWA.

Ọlọrun Yóo Bukun Àwọn Eniyan Rẹ̀

19 Ẹ̀yin ará Sioni tí ẹ̀ ń gbé Jerusalẹmu, ẹ kò ní sọkún mọ́. OLUWA yóo ṣàánú yín nígbà tí ẹ bá ké pè é, yóo sì da yín lóhùn nígbà tí ó bá gbọ́ igbe yín.

20 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé OLUWA yóo jẹ́ kí ẹ ní ọpọlọpọ ìṣòro, yóo sì jẹ́ kí ẹ ṣe ọpọlọpọ wahala, sibẹsibẹ olùkọ́ yín kò ní farapamọ́ fun yín mọ́, ṣugbọn ẹ óo máa fi ojú yín rí i.

21 Bí ẹ bá fẹ́ yapa sí apá ọ̀tún tabi apá òsì, ẹ óo máa gbọ́ ohùn kan lẹ́yìn yín tí yóo máa wí pé, “Ọ̀nà nìyí, ibí ni kí ẹ gbà.”

22 Àwọn oriṣa tí ẹ yọ́ fadaka bò, ati àwọn ère tí ẹ yọ́ wúrà bò yóo di nǹkan èérí lójú yín. Ẹ óo kọ̀ wọ́n sílẹ̀ bí nǹkan aláìmọ́. Ẹ óo sì wí fún wọn pé, “Ẹ pòórá!”

23 OLUWA yóo sì fi òjò ibukun sí orí èso tí ẹ gbìn sinu oko, nǹkan ọ̀gbìn yín yóo sì so lọpọlọpọ. Ní àkókò náà, àwọn ẹran ọ̀sìn yín tí yóo máa jẹ ní pápá oko yóo pọ̀.

24 Àwọn mààlúù ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí ẹ fí ń ṣe iṣẹ́ lóko yóo máa jẹ oko tí a fi iyọ̀ sí; tí a ti gbọn ìdọ̀tí kúrò lára rẹ̀.

25 Omi yóo máa ṣàn jáde láti orí gbogbo òkè gíga ati gbogbo òkè ńlá, ní ọjọ́ tí ọpọlọpọ yóo kú, nígbà tí ilé ìṣọ́ bá wó lulẹ̀.

26 Òṣùpá yóo mọ́lẹ̀ bí oòrùn; oòrùn yóo mọ́lẹ̀ ní ìlọ́po meje, ní ọjọ́ tí OLUWA yóo bá di ọgbẹ́ àwọn eniyan rẹ̀, tí yóo sì wo ọgbẹ́ tí ó dá sí wọn lára sàn.

Ọlọrun Yóo Jẹ Asiria níyà

27 Ẹ wo OLUWA tí ń bọ̀ láti ilẹ̀ òkèèrè,

ó ń bọ̀ tìbínú-tìbínú;

ninu èéfín ńlá tí ń lọ sókè.

Ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ kún fún ibinu;

ahọ́n rẹ̀ dàbí iná tí ń jóni run.

28 Èémí rẹ̀ dàbí odò tí ó ṣàn kọjá bèbè rẹ̀

tí ó lè mu eniyan dé ọrùn.

Yóo fi ajọ̀ ìparun jọ àwọn orílẹ̀-èdè,

yóo sì fi ìjánu tí ń múni ṣìnà bọ àwọn eniyan lẹ́nu.

29 Ẹ óo kọ orin kan bí orin alẹ́ ọjọ́ àjọ̀dún mímọ́,

inú yín yóo sì dùn bíi ti ẹni tí ń jó ijó fèrè lọ

sórí òkè OLUWA, àpáta Israẹli.

30 OLUWA yóo jẹ́ kí ẹ gbọ́ ohùn rẹ̀ tí ó lógo,

yóo sì jẹ́ kí ẹ rí ọwọ́ rẹ̀ tí yóo fà yọ pẹlu ibinu ńlá

ati ninu iná ajónirun;

pẹlu ẹ̀fúùfù ati ìjì líle ati òjò yìnyín.

31 Ìbẹ̀rù-bojo yóo mú àwọn ará Asiria

nígbà tí wọ́n bá gbóhùn OLUWA,

nígbà tí ó bá fi kùmọ̀ rẹ̀ lù wọ́n.

32 Ìró ọ̀pá tí OLUWA yóo fi nà wọ́n yóo dàbí ìró aro ati dùùrù.

OLUWA yóo dojú ogun kọ wọ́n.

33 Nítorí pé a ti pèsè iná ìléru sílẹ̀ láti ìgbà àtijọ́ fún ọba Asiria;

iná ńlá tí ń jó pẹlu ọpọlọpọ igi.

Èémí OLUWA tó dàbí ìṣàn imí-ọjọ́ ni yóo ṣá iná sí i.

Categories
AISAYA

AISAYA 31

Ọlọrun Yóo Dáàbò Bo Jerusalẹmu

1 Àwọn tí ó ń lọ sí Ijipti fún ìrànlọ́wọ́ gbé!

Àwọn tí wọ́n gbójú lé ẹṣin;

tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé kẹ̀kẹ́ ogun nítorí pé wọ́n pọ̀,

tí wọ́n gbójú lé ẹṣin

nítorí pé wọ́n lágbára!

Wọn kò gbójú lé Ẹni Mímọ́ Israẹli,

wọn kò sì wádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ OLUWA.

2 Bẹ́ẹ̀ ni ó gbọ́n,

ó sì mọ ọ̀nà tí ó fi lè mú kí àjálù dé bá eniyan,

kì í sọ̀rọ̀ tán, kó yí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pada.

Ṣugbọn yóo dìde sí ìdílé àwọn aṣebi,

ati àwọn tí ń ti àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ lẹ́yìn.

3 Eniyan sá ni àwọn ará Ijipti,

wọn kìí ṣe Ọlọrun.

Ẹranko lásán sì ni ẹṣin wọn

wọn kì í ṣe àǹjọ̀nnú.

Bí OLUWA bá na ọwọ́, tí ó bá gbá wọn mú,

ẹni tí ń ranni lọ́wọ́ yóo fẹsẹ̀ kọ,

ẹni tí à ń ràn lọ́wọ́ yóo ṣubú;

gbogbo wọn yóo sì jọ ṣègbé pọ̀.

4 Nítorí OLUWA sọ fún mi pé,

“Bí kinniun tabi ọmọ kinniun

ti máa ń kùn lórí ẹran tí ó bá pa,

tí kìí bìkítà fún igbe àwọn olùṣọ́ aguntan,

tí wọ́n pera wọn jọ, tí wọn ń bọ̀,

tí ẹ̀rù ariwo wọn kìí sìí bà á;

bẹ́ẹ̀ ni OLUWA àwọn ọmọ ogun yóo sọ̀kalẹ̀,

yóo wá jà lórí òkè Sioni ati àwọn òkè tí ó yí Sioni ká.

5 Bí àwọn ẹyẹ tií da ìyẹ́ bo ìtẹ́ wọn,

bẹ́ẹ̀ ni OLUWA àwọn ọmọ ogun

yóo dáàbò bo Jerusalẹmu,

yóo dáàbò bò ó, yóo sì gbà á sílẹ̀

yóo dá a sí, yóo sì yọ ọ́ kúrò ninu ewu.”

6 Ẹ̀yin ọmọ Israẹli,

ẹ pada sọ́dọ̀ ẹni tí ẹ ti ṣàìgbọràn sí lọpọlọpọ.

7 Nítorí pé ní ọjọ́ náà, olukuluku yóo gbé àwọn ère fadaka

ati ère wúrà tí ó fi ọwọ́ rẹ̀ ṣe sọnù,

àwọn ère tí ó mú wọn dẹ́ṣẹ̀.

8 Idà ni yóo pa Asiria, ṣugbọn kì í ṣe láti ọwọ́ eniyan;

idà tí kò ní ọwọ́ eniyan ninu ni yóo pa á run.

Yóo sá lójú ogun,

a óo sì kó àwọn ọmọkunrin rẹ̀ lọ máa ṣiṣẹ́ tipátipá.

9 Ẹ̀rù yóo ba ọba Asiria, yóo sálọ.

Ìpayà yóo mú kí àwọn ọ̀gágun rẹ̀ ju àsíá sílẹ̀.

OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀,

OLUWA tí iná rẹ̀ wà ní Sioni,

tí ojú ààrò rẹ̀ wà ní Jerusalẹmu.

Categories
AISAYA

AISAYA 32

Ọba tí ó ṣe é gbẹ́kẹ̀lé

1 Wò ó! Ọba kan yóo jẹ pẹlu òdodo,

àwọn ìjòyè yóo sì máa ṣe àkóso pẹlu ẹ̀tọ́.

2 Olukuluku yóo dàbí ibi ààbò nígbà tí ẹ̀fúùfù bá ń fẹ́

ati ibi ìsásí nígbà tí ìjì bá ń jà

Wọ́n óo dàbí odò ninu aṣálẹ̀,

ati bí ìbòòji àpáta ńlá nílẹ̀ olóoru.

3 Àwọn tí wọ́n bá rí i kò ní dijú sí i,

etí àwọn tí ó gbọ́ ọ kò ní di.

4 Àwọn tí kò ní àròjinlẹ̀ tẹ́lẹ̀ yóo ní òye,

àwọn akólòlò yóo sì sọ̀rọ̀ ketekete.

5 A kò ní máa pe aláìgbọ́n ní ọlọ́lá mọ́,

bẹ́ẹ̀ ni a kò ní máa pe abàlújẹ́ ní eniyan pataki.

6 Nítorí pé aláìgbọ́n ń sọ̀rọ̀ òmùgọ̀,

ọkàn rẹ̀ sì ń pète ibi.

Ó ń ro bí yóo ṣe hùwà ẹni tí kò mọ Ọlọrun,

tí yóo sọ̀rọ̀ ìsọkúsọ sí OLUWA;

tí yóo fi ẹni tí ebi ń pa sílẹ̀, láì fún un ní oúnjẹ,

tí yóo sì fi omi du ẹni òùngbẹ ń gbẹ.

7 Kìkì ibi ni èrò inú àwọn eniyankeniyan.

Wọn a máa pète ìkà,

láti fi irọ́ pa àwọn talaka run,

kì báà jẹ́ pé ẹjọ́ aláìní jàre.

8 Ṣugbọn eniyan rere a máa ro èrò rere,

ìdí nǹkan rere ni à á sì í bá wọn.

Ìdájọ́ ati Ìmúpadàbọ̀sípò

9 Ẹ dìde, ẹ̀yin obinrin tí ara rọ̀,

ẹ gbóhùn mi; ẹ̀yin ọmọbinrin tí ẹ wà ninu ìdẹ̀ra,

ẹ tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ mi.

10 Ní nǹkan bíi ọdún kan ó lé díẹ̀ sí i

ẹ̀yin obinrin tí ẹ wà ninu ìdẹ̀ra; ẹ ó rí ìdààmú

nítorí pé àkókò ìkórè yóo kọjá,

èso àjàrà kò sì ní sí lórí igi mọ́.

11 Ẹ gbọ̀n jìnnìjìnnì, ẹ̀yin obinrin tí ara rọ̀,

kí wahala ba yín, ẹ̀yin tí ẹ wà ninu ìdẹ̀ra,

ẹ tú aṣọ yín, kí ẹ wà ní ìhòòhò;

kí ẹ sì ró aṣọ ọ̀fọ̀.

12 Ẹ káwọ́ lérí, kí ẹ káàánú nítorí àwọn oko dáradára,

ati nítorí àwọn àjàrà eléso;

13 nítorí ẹ̀gún ẹ̀wọ̀n ati ẹ̀gún ọ̀gàn ni ó ń hù lórí ilẹ̀ àwọn eniyan mi.

Bákan náà, ẹ káàánú fún àwọn ilé aláyọ̀ ninu ìlú tí ó kún fún ayọ̀,

14 nítorí pé àwọn eniyan yóo sá kúrò ní ààfin,

ìlú yóo tú, yóo di ahoro.

Òkè ati ilé ìṣọ́ yóo di ibùgbé àwọn ẹranko títí lae,

yóo di ibi ìgbádùn fún àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ìgbẹ́,

ati pápá ibùjẹ fún àwọn ẹran ọ̀sìn.

15 Bẹ́ẹ̀ ni nǹkan yóo rí,

títí ẹ̀mí óo fi bà lé wa láti òkè ọ̀run wá

títí aṣálẹ̀ yóo fi di ọgbà eléso,

tí ọgbà eléso yóo sì fi di igbó.

16 A óo máa ṣe ìdájọ́ ẹ̀tọ́ ní gbogbo ilẹ̀ náà,

ìwà òdodo yóo sì wà níbi gbogbo.

17 Àyọrísí òdodo yóo sì jẹ́ alaafia,

ìgbẹ̀yìn rẹ̀ yóo sì jẹ́ ìbàlẹ̀ àyà wa,

ati igbẹkẹle OLUWA títí lae.

18 Àwọn eniyan mi yóo máa gbé pẹlu alaafia,

ní ibùgbé tí ó ní ààbò ati ibi ìsinmi tí ó ní ìbàlẹ̀ àyà.

19 Yìnyín yóo bọ́, yóo bo gbogbo ilẹ̀,

a óo sì pa ìlú náà run patapata.

20 Ayọ̀ ẹ̀yin tí ẹ̀ ń fúnrúgbìn sí etí odò yóo pọ̀,

ẹ̀yin tí ẹ ní mààlúù ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí ń jẹ káàkiri.

Categories
AISAYA

AISAYA 33

Adura fún Ìrànlọ́wọ́

1 O gbé! Ìwọ tí ń panirun,

tí ẹnìkan kò parun,

ìwọ tí ò ń hùwà ọ̀dàlẹ̀

nígbà tí ẹnìkan kò dà ọ́.

Ìgbà tí o bá dáwọ́ ìpanirun dúró,

nígbà náà ni a óo pa ìwọ gan-an run;

nígbà tí o bá fi ìwà ọ̀dàlẹ̀ sílẹ̀,

nígbà náà ni a óo dà ọ́.

2 Ṣàánú wa OLUWA,

ìwọ ni a dúró tí à ń wò.

Máa ràn wá lọ́wọ́ lojoojumọ,

sì máa jẹ́ olùgbàlà wa nígbà ìṣòro.

3 Àwọn orílẹ̀-èdè sá nígbà tí wọ́n gbọ́ ariwo tí ó dàbí ti ààrá,

wọ́n fọ́n ká nígbà tí o gbéra nílẹ̀.

4 A kó ìkógun jọ bí ìgbà tí tata bo oko,

àwọn eniyan dà bo ìṣúra, bí ìgbà tí eṣú bo oko.

5 A gbé OLUWA ga!

Nítorí pé ibi gíga ni ó ń gbé;

yóo mú kí ìdájọ́ òtítọ́ ati òdodo kún Sioni.

6 Yóo mú kí ìdúróṣinṣin wà ní gbogbo àkókò rẹ̀.

Yóo fún ọ ní ọpọlọpọ ìgbàlà, ati ọgbọ́n, ati ìmọ̀,

ìbẹ̀rù OLUWA ni ìṣúra rẹ̀.

7 Ẹ wò ó, àwọn alágbára ń kígbe lóde,

àwọn òjíṣẹ́ alaafia ń sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn.

8 Òpópó ọ̀nà ṣófo,

àwọn èrò kò rìn mọ́;

wọ́n ń ba majẹmu jẹ́,

wọn kò bìkítà fún ẹlẹ́rìí mọ́;

wọ́n kò sì ka eniyan sí.

9 Ilẹ̀ ṣófo ó sì gbẹ,

ìtìjú bá òkè Lẹbanoni,

gbogbo ewéko orí rẹ̀ sì rẹ̀ dànù.

Ṣaroni dàbí aṣálẹ̀,

igi igbó Baṣani ati ti òkè Kamẹli sì wọ́wé.

OLUWA Kìlọ̀ fún Àwọn Ọ̀tá Rẹ̀

10 OLUWA ní:

“Ó yá tí n óo dìde,

ó yá mi wàyí, n óo gbéra nílẹ̀.

Àsìkò tó tí a óo gbé mi ga.

11 Èrò yín dàbí fùlùfúlù, gbogbo ìṣe yín dàbí pòpórò ọkà.

Èémí mi yóo jó yín run bí iná.

12 Àwọn orílẹ̀-èdè yóo dàbí ìgbà tí a sun wọ́n,

tí wọ́n di eérú,

àní bí igi ẹ̀gún tí a gé lulẹ̀, tí a sì dáná sun.

13 Ẹ̀yin tí ẹ wà lókè réré,

ẹ gbọ́ ohun tí mo ṣe;

ẹ̀yin tí ẹ wà nítòsí,

ẹ kíyèsí agbára mi.”

14 Ẹ̀rù ń ba àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí ó wà ní Sioni;

ìjayà mú àwọn ẹni tí kò mọ Ọlọrun.

Ta ni ninu wa ló lè gbé inú iná ajónirun?

Ta ni ninu wa ló lè gbé inú iná àjóòkú?

15 Ẹni tí ọ̀nà rẹ̀ bá tọ́, tí ó sì ń sọ ọ̀rọ̀ òtítọ́,

ẹni tí ó kórìíra èrè àjẹjù,

tí ó kọ̀, tí kò gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀,

tí ó di etí sí ọ̀rọ̀ àwọn tí ń gbèrò ati paniyan,

tí ó sì di ojú rẹ̀ kí ó má baà rí nǹkan ibi.

16 Ibi ààbò ni yóo máa gbé, àpáta ńlá ni yóo jẹ́ ibi ààbò rẹ̀.

Yóo máa rí oúnjẹ jẹ déédé,

yóo sì máa rí omi mu lásìkò, lásìkò.

Ọjọ́ Ọ̀la tó Lógo

17 Ojú yín yóo rí ọba ninu ọlá ńlá rẹ̀;

ẹ óo fojú yín rí ilẹ̀ tí ó lọ salalu.

18 Ẹ óo máa ronú ìnira tí ẹ ti ní pé:

“Níbo ni akọ̀wé wà?

Níbo ni ẹni tí ń gba owó orí wà?

Níbo sì ni ẹni tí ń ka ilé ìṣọ́ wà?”

19 Ẹ kò ní rí àwọn aláfojúdi náà mọ́,

àwọn tí wọn ń fọ èdè tí kò ní ìtumọ̀ si yín,

tí wọn ń kólòlò ní èdè tí ẹ kò gbọ́.

20 Ẹ wo Sioni, ìlú tí a yà sọ́tọ̀ fún àjọ̀dún.

Ẹ óo fi ojú rí Jerusalẹmu, ibùgbé alaafia, tí àgọ́ rẹ̀ kò ní ṣídìí,

tí èèkàn tí a fi kàn án mọ́lẹ̀ kò ní hú laelae,

bẹ́ẹ̀ ni okùn tí a fi so ó mọ́lẹ̀ kò ní já.

21 Ṣugbọn níbẹ̀ ni OLUWA, ninu ògo rẹ̀,

yóo jẹ́ odò ńlá ati odò tí ń ṣàn fún wa;

níbi tí ọkọ̀ ọlọ́pọ́n kò lè dé,

ọkọ̀ ojú omi kò sì ní lè kọjá níbẹ̀.

22 Nítorí pé OLUWA ni onídàájọ́ wa,

òun ni alákòóso wa;

OLUWA ni ọba wa,

òun ni yóo gbà wá là.

23 Okùn òpó-ọkọ̀ rẹ̀ ti tú,

kò lè mú òpó-ọkọ̀ náà dáradára ní ipò rẹ̀ mọ́;

kò sì lè gbé ìgbòkun dúró.

A óo pín ọpọlọpọ ìkógun nígbà náà,

kódà, àwọn arọ pàápàá yóo pín ninu rẹ̀.

24 Kò sí ará ìlú kan tí yóo sọ pé,

“Ara mi kò yá.”

A óo dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn tí ń gbé ibẹ̀ jì wọ́n.

Categories
AISAYA

AISAYA 34

Ọlọrun Yóo Jẹ Àwọn Ọ̀tá Rẹ̀ níyà

1 Ẹ súnmọ́ ibí, kí ẹ wá gbọ́, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè,

ẹ tẹ́tí sílẹ̀, gbogbo ẹ̀yin eniyan.

Kí ilẹ̀ gbọ́ ati gbogbo ohun tí ó wà lórí rẹ̀,

kí ayé tẹ́tí sílẹ̀ pẹlu gbogbo nǹkan tí ń ti inú rẹ̀ jáde.

2 Nítorí OLUWA ń bínú sí gbogbo orílẹ̀-èdè,

inú rẹ̀ sì ń ru sí àwọn eniyan ibẹ̀.

Ó ti fi wọ́n sílẹ̀ fún ìparun, ó sì ti fà wọ́n kalẹ̀ fún pípa.

3 A óo wọ́ òkú wọn jùnù,

òkú wọn yóo máa rùn;

ẹ̀jẹ̀ wọn yóo sì máa ṣàn lórí àwọn òkè.

4 Oòrùn, òṣùpá, ati àwọn ìràwọ̀ yóo gbọ̀n dànù

a óo ká awọsanma bí ẹni ká ìwé.

Oòrùn, òṣùpá, ati àwọn ìràwọ̀ yóo jábọ́

bí ewé tií rẹ̀ sílẹ̀ lára ìtàkùn àjàrà,

àní, bí ewé tií wọ́ dànù lórí igi ọ̀pọ̀tọ́.

5 Nítorí mo ti rẹkẹ idà mi lókè ọ̀run,

yóo sọ̀kalẹ̀ láti ṣe ìdájọ́ àwọn ará Edomu;

yóo sọ̀kalẹ̀ sórí àwọn tí mo fẹ́ parun.

6 OLUWA ní idà kan tí a tì bọ inú ẹ̀jẹ̀,

a rì í sinu ọ̀rá,

pẹlu ẹ̀jẹ̀ ọ̀dọ́ aguntan ati ti ewúrẹ́,

ati ọ̀rá ara kíndìnrín àgbò.

Nítorí pé OLUWA yóo rú ẹbọ ní Bosira,

yóo sì pa ọpọlọpọ eniyan ní ilẹ̀ Edomu.

7 Àwọn mààlúù igbó yóo kú pẹlu wọn,

bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ẹgbọ̀rọ̀ mààlúù ati àwọn akọ mààlúù ńlá.

Ilẹ̀ wọn yóo kún fún ẹ̀jẹ̀,

ọ̀rá eniyan yóo sì mú kí ilẹ̀ wọn lẹ́tù lójú.

8 Nítorí OLUWA ti ya ọjọ́ kan sọ́tọ̀ fún ẹ̀san,

ó ti ya ọdún kan sọ́tọ̀ tí yóo gbèjà Sioni.

9 Àwọn odò ilẹ̀ Edomu yóo di ọ̀dà,

erùpẹ̀ rẹ̀ yóo di imí ọjọ́;

ilẹ̀ Edomu yóo di ọ̀dà tí ń jó bùlàbùlà.

10 Yóo máa jó tọ̀sán-tòru, kò ní kú,

yóo máa rú èéfín sókè títí lae.

Yóo di aṣálẹ̀ láti ìrandíran,

ẹnikẹ́ni kò ní gbabẹ̀ kọjá mọ́ títí lae.

11 Àṣá ati òòrẹ̀ ni yóo fi ibẹ̀ ṣe ilé,

òwìwí ati ẹyẹ kannakánná ni yóo máa gbé ibẹ̀.

OLUWA yóo ta okùn ìdàrúdàpọ̀ lé e lórí,

yóo sì na ọ̀pá ìdàrúdàpọ̀ lé àwọn ìjòyè rẹ̀ lórí.

12 “Kò sí Ilẹ̀ Ọba Mọ́” ni a óo máa pè é.

Gbogbo àwọn ìjòyè rẹ̀ yóo parẹ́.

13 Ẹ̀gún yóo hù ninu ààfin rẹ̀,

ẹ̀gún òṣùṣú ati ẹ̀gún ọ̀gàn yóo hù ninu àwọn ìlú olódi rẹ̀.

Wọn yóo di ibùgbé fún àwọn ọ̀fàfà ati ẹyẹ ògòǹgò,

14 àwọn ẹranko ìgbẹ́ ati ìkookò yóo jọ máa gbé ibẹ̀,

àwọn ewúrẹ́ igbó yóo máa ké pe ara wọn.

Iwin yóo rí ibi máa gbé,

yóo sì rí ààyè máa sinmi níbẹ̀.

15 Òwìwí yóo pa ìtẹ́ sibẹ, tí yóo máa yé sí.

Yóo pamọ, yóo ràdọ̀ bo àwọn ọmọ rẹ̀,

yóo sì máa tọ́jú wọn níbẹ̀.

Àwọn àṣá yóo péjọ sibẹ,

olukuluku wọn, pẹlu ekeji rẹ̀.

16 Ẹ lọ wá inú ìwé OLUWA,

kí ẹ ka ohun tí ó wà níbẹ̀.

Kò sí ọ̀kan ninu àwọn wọnyi tí kò ní sí níbẹ̀,

kò sí èyí tí kò ní ní ẹnìkejì.

Nítorí OLUWA ni ó pàṣẹ bẹ́ẹ̀,

ẹ̀mí rẹ̀ ni ó sì kó wọn jọ.

17 Ó ti ṣẹ́ gègé fún wọn,

ó ti fi okùn wọ̀n ọ́n kalẹ̀ fún wọn.

Àwọn ni wọn óo ni ín títí lae,

wọn óo sì máa gbé ibẹ̀ láti ìrandíran.

Categories
AISAYA

AISAYA 35

Ọ̀nà Ìwà Mímọ́

1 Inú aṣálẹ̀ ati ilẹ̀ gbígbẹ yóo dùn,

aṣálẹ̀ yóo yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀, yóo rúwé, yóo sì tanná.

2 Nítòótọ́ yóo tanná bí òdòdó,

yóo yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀, yóo sì kọrin.

Ògo Lẹbanoni yóo di tìrẹ

ati iyì Kamẹli ati ti Ṣaroni.

Wọn óo rí ògo OLUWA,

wọn óo rí ọlá ńlá Ọlọrun wa.

3 Ẹ gbé ọwọ́ tí kò lágbára ró.

Ẹ fún orúnkún tí kò lágbára ní okun.

4 Ẹ sọ fún àwọn tí àyà wọn ń já pé:

“Ẹ ṣe ara gírí, ẹ má bẹ̀rù.

Ẹ wò ó! Ọlọrun yín óo wá pẹlu ẹ̀san,

ó ń bọ̀ wá gbẹ̀san gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun;

ó ń bọ̀ wá gbà yín là.”

5 Ojú afọ́jú yóo là nígbà náà,

etí adití yóo sì ṣí;

6 arọ yóo máa fò bí ìgalà,

odi yóo sì máa kọ orin ayọ̀.

Nítorí odò ńlá yóo ṣàn jáde ninu aginjù

àwọn odò kéékèèké yóo máa ṣàn ninu aṣálẹ̀.

7 Ilẹ̀ iyanrìn gbígbóná yóo di adágún omi

ilẹ̀ gbígbẹ yóo di orísun omi,

ibi tí ọ̀fàfà fi ṣe ilé tẹ́lẹ̀ yóo di àbàtà,

èèsún ati ìyè yóo máa dàgbà níbẹ̀.

8 Òpópónà kan yóo wà níbẹ̀,

a óo máa pè é ní Ọ̀nà Ìwà Mímọ́;

nǹkan aláìmọ́ kan kò ní gba ibẹ̀ kọjá,

àwọn aláìgbọ́n kò sì ní dẹ́ṣẹ̀ níbẹ̀.

9 Kò ní sí kinniun níbẹ̀,

bẹ́ẹ̀ ni ẹranko burúkú kankan kò ní gba ibẹ̀.

A kò ní rí wọn níbẹ̀,

àwọn tí a ti rà pada ni yóo gba ibẹ̀.

10 Àwọn tí OLUWA rà pada yóo pada,

wọn óo wá sí Sioni pẹlu orin,

ayọ̀ ayérayé yóo kún inú wọn.

Wọn óo rí ayọ̀ ati ìdùnnú gbà

ìbànújẹ́ ati òṣé yóo sá kúrò níbẹ̀.

Categories
AISAYA

AISAYA 36

Àwọn Ará Asiria Halẹ̀ mọ́ Jerusalẹmu

1 Ní ọdún kẹrinla tí Ọba Hesekaya jọba, Senakeribu, ọba Asiria gbógun ti gbogbo ìlú olódi Juda, ó sì kó wọn.

2 Ọba Asiria rán Rabuṣake (olórí ogun rẹ̀), pẹlu ọpọlọpọ ọmọ ogun; láti Lakiṣi sí ọba Hesekaya ní Jerusalẹmu. Nígbà tí wọn dé ibi tí omi tí ń ṣàn wọ ìlú láti orí òkè tí ó wà ní ọ̀nà pápá alágbàfọ̀, wọ́n dúró níbẹ̀.

3 Eliakimu, ọmọ Hilikaya tí ó jẹ́ alákòóso ààfin jáde lọ bá wọn pẹlu Ṣebina, akọ̀wé ilé ẹjọ́, ati Joa ọmọ Asafu, akọ̀wé ààfin.

4 Rabuṣake bá sọ fún wọn pé, “Ẹ sọ fún Hesekaya pé ọba ńlá Asiria ní kí ló gbójú lé rí?

5 Ó ní ṣé Hesekaya rò pé ọ̀rọ̀ ẹnu ni ọgbọ́n ati agbára tí wọ́n fi ń jagun ni; àbí ta ló gbójú lé tí ó fi ń ṣàìgbọràn sí òun?

6 Ó ní Ijipti tí Hesekaya gbára lé dàbí kí eniyan fi ìyè ṣe ọ̀pá ìtẹ̀lẹ̀, ìyè tí yóo dá, tí yóo sì gún ẹnikẹ́ni tí ó bá gbára lé e lọ́wọ́. Bẹ́ẹ̀ ni Farao ọba Ijipti jẹ́ sí gbogbo àwọn tí ó bá gbára lé e.

7 “Ó ní bí Hesekaya bá sì sọ fún òun pé, OLUWA Ọlọrun àwọn ni àwọn gbójú lé, òun óo bi í pé, ṣé kì í ṣe ojúbọ OLUWA náà ati àwọn pẹpẹ ìrúbọ rẹ̀ ni Hesekaya wó lulẹ̀ nígbà tí ó sọ fún àwọn ará Juda ati àwọn ará Jerusalẹmu pé, ẹyọ pẹpẹ kan ni kí wọ́n ti máa sin OLUWA?”

8 Rabuṣake ní, “Mo fẹ́ kí Hesekaya bá oluwa mi, ọba Asiria, ṣe pàṣípààrọ̀ kan, n óo fún un ní ẹgbaa ẹṣin bí ó bá lè rí eniyan tó tí ó lè gùn wọ́n.

9 Báwo ni ó ṣe lè lé ẹni tí ó kéré jù ninu àwọn olórí-ogun oluwa mi pada sẹ́yìn, nígbà tí ó jẹ́ pé Ijipti ni ó gbójú lé pé wọn óo fún un ní kẹ̀kẹ́ ogun ati àwọn ẹlẹ́ṣin?

10 Ẹ bi í pé, ṣé kò mọ̀ pé wíwá tí mo wá láti gbógun ti ìlú yìí ati láti pa á run kò ṣẹ̀yìn OLUWA? OLUWA ni ó sọ fún mi pé kí n lọ gbógun ti ilẹ̀ yìí, kí n sì pa á run.”

11 Nígbà náà ni Eliakimu ati Ṣebina ati Joa sọ fún Rabuṣake pé, “Jọ̀wọ́, èdè Aramaiki ni kí o fi bá wa sọ̀rọ̀, nítorí pé àwa náà gbọ́ Aramaiki. Má fi èdè Juda bá wa sọ̀rọ̀ kí àwọn ará wa tí ó wà lórí odi má baà gbọ́.”

12 Ṣugbọn Rabuṣake dá wọn lóhùn pé, “Ṣé ẹ rò pé ẹ̀yin ati oluwa yín nìkan ni oluwa mi rán mi pé kí n jíṣẹ́ yìí fún ni? Ṣé kò yẹ kí gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n jókòó lórí odi ìlú yìí fetí wọn gbọ́ pé, ati àwọn ati ẹ̀yin, ẹ ti gbé, ẹ o máa jẹ ìgbọ̀nsẹ̀ ara yín, ẹ óo sì máa mu ìtọ̀ yín?”

13 Rabuṣake bá dìde dúró, ó sì kígbe ní èdè Juda, ó ní, “Ẹ gbọ́ ohun tí ọba ńlá, ọba Asiria wí:

14 Ọba ní kí ẹ má ṣe jẹ́ kí Hesekaya tàn yín jẹ, nítorí kò ní le gbà yín là.

15 Ẹ má ṣe jẹ́ kí Hesekaya mú kí ẹ gbẹ́kẹ̀lé OLUWA, kí ó máa wí fún yín pé, ‘Dájúdájú OLUWA yóo gbà wá, ọba Asiria kò ní fi ogun kó ìlú yìí.’

16 “Ẹ má fetí sí ọ̀rọ̀ Hesekaya; nítorí ọba Asiria ní kí ẹ bá òun ṣe àdéhùn alaafia kí ẹ jáde tọ òun wá. Bí ẹ bá ṣe bẹ́ẹ̀, olukuluku yín ni yóo máa jẹ èso àjàrà ati èso ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀, olukuluku yín yóo sì máa mu omi ninu kànga rẹ̀;

17 títí òun óo fi wá mú yín lọ sí ilẹ̀ mìíràn tí ó dàbí ilẹ̀ yín, ilẹ̀ tí ó kún fún ọkà ati ọtí, tí oúnjẹ ati ọgbà àjàrà ti pọ̀.

18 Ẹ ṣọ́ra kí Hesekaya má baà fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣì yín lọ́nà, kí ó máa sọ pé, ‘OLUWA yóo gbà wá.’ Ṣé ọ̀kankan ninu àwọn oriṣa àwọn orílẹ̀-èdè yòókù ti gba ilẹ̀ rẹ̀ sílẹ̀ lọ́wọ́ Ọba Asiria rí?

19 Àwọn oriṣa Hamati ati Aripadi dà? Níbo ni àwọn oriṣa Sefafaimu wà? Ṣé wọn gba àwọn ará Samaria kalẹ̀ lọ́wọ́ mi?

20 Èwo ninu àwọn oriṣa ilẹ̀ wọnyi ni ó gba ilẹ̀ rẹ̀ kalẹ̀ lọ́wọ́ mi, tí ẹ fi rò pé OLUWA yóo gba Jerusalẹmu kalẹ̀ lọ́wọ́ mi?”

21 Gbogbo wọn dákẹ́, kò sí ẹnìkan tí ó sọ nǹkankan nítorí ọba ti pàṣẹ pé ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ dá a lóhùn.

22 Eliakimu, ọmọ Hilikaya tí ó jẹ́ alákòóso ààfin ati Ṣebina, akọ̀wé ilé ẹjọ́, ati Joa, ọmọ Asafu, akọ̀wé ààfin wá sọ́dọ̀ Hesekaya pẹlu àwọn ti aṣọ wọn tí wọ́n ti fàya láti fi ìbànújẹ́ wọn hàn, wọ́n sì sọ ohun tí Rabuṣake wí fún un.

Categories
AISAYA

AISAYA 37

Ọba Bèèrè Ìmọ̀ràn lọ́wọ́ Aisaya

1 Nígbà tí Hesekaya ọba gbọ́, ó fa aṣọ rẹ̀ ya, ó fi aṣọ ọ̀fọ̀ bora, ó sì wọ inú ilé OLUWA lọ.

2 Ó rán Eliakimu tí ń ṣàkóso ààfin, ati Ṣebina akọ̀wé ilé ẹjọ́ ati àwọn àgbààgbà alufaa, wọ́n da aṣọ ọ̀fọ̀ bora, wọ́n lọ sọ́dọ̀ wolii Aisaya, ọmọ Amosi.

3 Wọ́n jíṣẹ́ fún un, wọ́n ní, “Hesekaya ní kí á sọ fún ọ pé: ‘Ọjọ́ ìṣòro ni ọjọ́ òní, ọjọ́ ìyà, ati ọjọ́ ẹ̀sín. Ọmọ ń mú aboyún, ó dé orí ìkúnlẹ̀, ṣugbọn kò sí agbára láti bíi.

4 Ó ṣeéṣe kí OLUWA Ọlọrun rẹ ti gbọ́ iṣẹ́ tí ọba Asiria rán Rabuṣake, iranṣẹ rẹ̀, pé kí ó wá fi Ọlọrun alààyè ṣe ẹlẹ́yà, kí OLUWA Ọlọrun rẹ ṣe ìdájọ́ tí ó tọ́ lórí irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀! Nítorí náà gbé ohùn ẹ̀bẹ̀ sókè kí o gbadura fún àwọn eniyan tí ó kù.’ ”

5 Nígbà tí àwọn oníṣẹ́ Hesekaya ọba jíṣẹ́ fún Aisaya,

6 Aisaya dá wọn lóhùn pé, “Ẹ wí fún oluwa yín pé OLUWA ní:

‘Má bẹ̀rù nítorí ọ̀rọ̀ tí o gbọ́

tí iranṣẹ ọba Asiria sọ tí ó ń fi mí ṣe ẹlẹ́yà.

7 Ìwọ máa wò ó, n óo fi ẹ̀mí kan sí inú rẹ̀,

yóo gbọ́ ìròyìn èké kan,

yóo sì pada lọ sí ilẹ̀ rẹ̀.

Nígbà tí ó bá dé ilé

n óo jẹ́ kí wọ́n fi idà pa á.’ ”

Àwọn Ará Asiria Tún Halẹ̀ Lẹẹkeji

8 Rabuṣake gbọ́ pé ọba Asiria ti kúrò ní Lakiṣi, nítorí náà, ó lọ bá a níbi tí ó ti ń bá àwọn ará Libina jagun.

9 Ibẹ̀ ni àwọn kan ti ròyìn fún ọba Asiria pé, Tirihaka ọba Etiopia ń bọ̀ wá gbógun tì í. Nígbà tí ó gbọ́, ó rán ikọ̀ lọ bá Hesekaya, ó ní:

10 “Ẹ sọ fún Hesekaya ọba Juda pé kí ó má jẹ́ kí Ọlọrun rẹ̀ tí ó gbójú lé ṣì í lọ́nà kí ó sọ pé ọba Asiria kò ní fi ogun kó Jerusalẹmu.

11 Ṣebí Hesekaya ti gbọ́ ohun tí àwọn ọba Asiria ṣe sí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè, tí wọ́n pa wọ́n run patapata. Ṣé Hesekaya rò pé a óo gba òun là ni?

12 Ṣé àwọn oriṣa orílẹ̀-èdè tí àwọn baba ńlá mi parun gbà wọ́n sílẹ̀, àwọn orílẹ̀-èdè bíi Gosani ati Harani, Resefu ati àwọn ará Edẹni tí ń gbé Telasari?

13 Ọba Hamati dà? Ọba Aripadi ńkọ́? Níbo ni ọba ìlú Sefafaimu ati ọba Hena ati ọba Ifa wà?”

Adura Hesekaya

14 Hesekaya gba ìwé náà lọ́wọ́ àwọn ikọ̀ ọba Asiria, ó kà á. Nígbà tí ó kà á tán, ó gbéra, ó lọ sí ilé OLUWA, ó bá tẹ́ ìwé náà sílẹ̀ níwájú OLUWA,

15 Hesekaya bá gbadura sí OLUWA, ó ní:

16 “Ìwọ OLUWA àwọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israẹli, ìwọ tí ìtẹ́ rẹ wà lórí àwọn Kerubu, ìwọ nìkan ni Ọlọrun gbogbo ìjọba ayé, ìwọ ni ó sì dá ọ̀run ati ayé.

17 Dẹtí sílẹ̀ OLUWA, kí o gbọ́. La ojú rẹ, OLUWA, kí o máa wo nǹkan. Gbọ́ irú iṣẹ́ tí Senakeribu rán tí ó ń fi ìwọ Ọlọrun alààyè ṣe ẹlẹ́yà.

18 Lóòótọ́ ni, OLUWA, pé àwọn ọba Asiria ti pa gbogbo orílẹ̀-èdè run tàwọn ti ilẹ̀ wọn,

19 ati pé wọ́n ju oriṣa wọn sinu iná, nítorí pé wọn kì í ṣe Ọlọrun. Iṣẹ́ ọwọ́ eniyan ni wọ́n, tí wọ́n fi igi ati òkúta ṣe, nítorí náà ni wọ́n ṣe lè pa wọ́n run.

20 Nisinsinyii, OLUWA Ọlọrun wa, gbà wá lọ́wọ́ rẹ̀, kí gbogbo ìjọba ayé lè mọ̀ pé ìwọ nìkan ni OLUWA.”

Aisaya Ranṣẹ Pada sí Ọba

21 Aisaya ọmọ Amosi bá ranṣẹ sí Hesekaya, pé OLUWA, Ọlọrun Israẹli ní, nítorí pé Hesekaya ti gbadura sí òun nípa Senakeribu ọba Asiria,

22 ohun tí OLUWA sọ nípa rẹ̀ ni pé:

“Sioni bu ẹnu àtẹ́ lù ọ́, Senakeribu,

ó fi ọ́ ṣe ẹlẹ́yà,

Jerusalẹmu ń yọ ṣùtì sí ọ.

23 Ta ni ò ń sọ̀rọ̀ aṣa sí, tí ò ń fí ń ṣe ẹlẹ́yà?

Ta ni ò ń ṣíjú wò pẹlu ìgbéraga?

Ṣé Ẹni Mímọ́ Israẹli ni o ṣe irú èyí sí?

24 O rán àwọn iranṣẹ rẹ láti fi OLUWA ṣe ẹlẹ́yà,

o ní,

‘Mo ti fi ọpọlọpọ kẹ̀kẹ́ ogun mi gun orí àwọn òkè gíga lọ,

mo dé góńgó orí òkè Lẹbanoni.

Mo ti gé àwọn igi kedari rẹ̀ tí ó ga jùlọ lulẹ̀,

ati àwọn ààyò igi firi rẹ̀.

Mo ti dé ibi tí ó ga jùlọ ní ilẹ̀ rẹ̀,

ati igbó rẹ̀ tí ó dí jùlọ.

25 Mo gbẹ́ kànga mo sì mu omi ninu wọn.

Mo ti fi ẹsẹ̀ mi tẹ gbogbo omi odò kéékèèké ilẹ̀ Ijipti ní àtẹ̀gbẹ.’

26 “Ṣé o kò tíì gbọ́ pé láti ìgbà pípẹ́,

ni mo ti pinnu ohun tí mò ń mú ṣẹ nisinsinyii?

Láti ayébáyé ni mo ti ṣètò rẹ̀,

pé kí o wó ìlú olódi palẹ̀,

kí ó di òkítì àlàpà.

27 Kí àwọn eniyan tí ń gbé inú wọn

má ní agbára mọ́,

kí wọ́n wà ninu ìdààmú ati ìpayà.

Kí wọ́n dàbí ewé inú oko

ati bíi koríko tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ hù

bí koríko tí ó hù lórí òrùlé,

tíí gbẹ kí ó tó dàgbà.

28 “Mo mọ ìjókòó rẹ.

Mo mọ ìjáde ati ìwọlé rẹ,

ati inú tí ò ń bá mi bí.

29 Nítorí pé ò ń bá mi bínú,

mo sì ti gbọ́ nípa ìwà ìgbéraga rẹ,

n óo sì fi ìwọ̀ kọ́ ọ ní imú,

n óo fi ìjánu bọ̀ ọ́ ni ẹnu,

n óo sì dá ọ pada sí ọ̀nà tí o gbà wá.

30 “Ohun tí yóo jẹ́ àmì fún ọ nìyí Hesekaya: Ní ọdún yìí, ohun tí ó bá lalẹ̀ hù ni ẹ óo máa jẹ. Ní ọdún tí ń bọ̀ pẹlu, ohun tí ó bá lalẹ̀ hù ni ẹ óo máa jẹ bákan náà. Ní ọdún kẹta, ẹ gbin nǹkan ọ̀gbìn, kí ẹ sì kórè rẹ̀, ẹ ṣe ọgbà àjàrà kí ẹ sì máa jẹ èso inú rẹ̀.

31 Àwọn ọmọ Juda tí ó bá ṣẹ́kù yóo fi gbòǹgbò múlẹ̀, wọn óo sì so èso.

32 Àwọn eniyan yóo ṣẹ́kù tí yóo wá láti Jerusalẹmu àwọn tí wọn yóo sá àsálà yóo wá láti orí òkè Sioni. Ìtara OLUWA àwọn ọmọ ogun ni yóo ṣe èyí.

33 “Nítorí náà, ohun tí OLUWA wí nípa ọba Asiria ni pé, ‘Kò ní wọ inú ìlú yìí, kò sì ní ta ọfà sí i. Àwọn ọmọ ogun rẹ̀ kò ní kó apata wọ inú rẹ̀. Wọn kò sì ní dó tì í.

34 Ọ̀nà tí ọba Asiria gbà wá ni yóo gbà pada lọ, kò ní fi ẹsẹ̀ kan inú ìlú yìí.

35 N óo dáàbò bo ìlú yìí, n óo sì gbà á sílẹ̀ nítorí tèmi ati nítorí Dafidi iranṣẹ mi.’ ”

36 Angẹli OLUWA bá lọ sí ibùdó àwọn ọmọ ogun Asiria, ó sì pa ọ̀kẹ́ mẹsan-an ó lé ẹgbẹẹdọgbọn (185,000) ninu wọn. Nígbà tí wọn jí ní àfẹ̀mọ́júmọ́ òkú kún ilẹ̀ lọ kítikìti.

37 Senakeribu ọba Asiria bá pada sílé, ó ń lọ gbé ìlú Ninefe.

38 Ní ọjọ́ kan, ó lọ bọ Nisiroku, oriṣa rẹ̀, àwọn meji ninu àwọn ọmọ rẹ̀: Adirameleki ati Ṣareseri, sì fi idà gún un pa, wọ́n bá sá lọ sí ilẹ̀ Ararati. Esaradoni ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.

Categories
AISAYA

AISAYA 38

Àìsàn Hesekaya ati Ìmúláradá Rẹ̀

1 Ní àkókò náà, Hesekaya ṣàìsàn, àìsàn náà pọ̀; ó fẹ́rẹ̀ kú. Aisaya wolii, ọmọ Amosi tọ̀ ọ́ wá ní ọjọ́ kan, ó wí fún un pé: “OLUWA ní kí n sọ fún ọ pé kí o ṣe ètò ilé rẹ, nítorí pé o óo kú ni, o kò ní yè.”

2 Hesekaya bá kọjú sí ògiri, ó gbadura sí OLUWA,

3 ó ní, “OLUWA, dákun, mo bẹ̀ ọ́ ni, ranti bí mo ti ṣe fi tọkàntọkàn rìn níwájú rẹ pẹlu òtítọ́ inú, tí mo sì ṣe ohun tí ó tọ́ lójú rẹ.” Hesekaya bá sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn.

4 OLUWA bá sọ fún Aisaya pé

5 kí ó lọ sọ fún Hesekaya pé, òun, OLUWA Ọlọrun Dafidi baba ńlá rẹ̀ ti gbọ́ adura rẹ̀. Oun ti rí omijé rẹ̀, òun óo sì fi ọdún mẹẹdogun kún ọjọ́ ayé rẹ̀.

6 OLUWA ní òun óo gba Hesekaya lọ́wọ́ ọba Asiria, òun óo gbèjà ìlú Jerusalẹmu, òun óo sì dáàbò bò ó.

21 Aisaya bá sọ fún Hesekaya pé kí wọn bá a wá èso ọ̀pọ̀tọ́ kí wọn lọ̀ ọ́, kí wọn fi lé ojú oówo tí ó mú un, kí ó lè gbádùn.

22 Hesekaya bá bèèrè pé, kí ni àmì tí òun óo fi mọ̀ pé òun óo tún fi ẹsẹ̀ òun tẹ ilé Olúwa?

7 Aisaya ní, àmì tí OLUWA fún Hesekaya tí yóo mú kí ó dá a lójú pé òun OLUWA yóo ṣe ohun tí òun ṣèlérí nìyí:

8 Òun óo mú kí òjìji oòrùn ìrọ̀lẹ́ pada sẹ́yìn ní àtẹ̀gùn mẹ́wàá lórí àtẹ̀gùn Ahasi. Oòrùn bá yí pada nítòótọ́, òjìji sì pada sẹ́yìn ní àtẹ̀gùn mẹ́wàá tí ó ti sọ tẹ́lẹ̀.

Orin Ọpẹ́ tí Hesekaya kọ

9 Orin tí Hesekaya ọba Juda kọ sílẹ̀ nígbà tí ó ṣàìsàn tí Ọlọrun sì wò ó sàn nìyí:

10 Mo ti rò pé n óo kú lọ́jọ́ àìpé,

ati pé a óo sé mi mọ́ inú ibojì,

níbẹ̀ ni n óo sì ti lo ìyókù ọjọ́ ayé mi.

11 Mo rò pé n kò ní tún fojú kan OLUWA mọ́ ní ilẹ̀ alààyè,

ati pé n kò ní sí láàyè mọ́

láti tún fi ojú mi kan ẹnikẹ́ni.

12 A tú àgọ́ mi palẹ̀ bí àgọ́ darandaran,

a sì ká a lọ kúrò lọ́dọ̀ mi.

Mo ká ayé mi bí aṣọ tí wọn ń hun.

Ó sì gé mi kúrò bí aṣọ tí wọ́n gé kúrò lórí òfì.

Mo ti kọ́ rò pé tọ̀sán-tòru ni ìwọ OLUWA ń fi òpin sí ayé mi.

13 Mo kígbe fún ìrànlọ́wọ́ títí ilẹ̀ fi mọ́

ó fọ́ gbogbo egungun mi bí kinniun ti máa ń fọ́ egungun.

Tọ̀sán-tòru mo rò pé Ọlọrun ń fi òpin sí ayé mi ni.

14 Ọkàn mi ń ṣe hílàhílo bí ẹyẹ aláàpáǹdẹ̀dẹ̀ ati ẹyẹ àkọ̀,

mò ń ké igbe arò bí àdàbà.

Mo wòkè títí ojú ń ro mí,

ara ń ní mí, OLUWA, nítorí náà ṣe ààbò mi.

15 Ṣugbọn kí ni mo lè sọ?

Nítorí pé ó ti bá mi sọ̀rọ̀,

òun fúnrarẹ̀ ni ó sì ṣe é

Oorun kò kùn mí nítorí pé ọkàn mi bàjẹ́.

16 OLUWA, nǹkan wọnyi ni ó mú eniyan wà láàyè,

ninu gbogbo rẹ̀ èmi náà yóo wà láàyè.

Áà, jọ̀wọ́ wò mí sàn, kí o mú mi wà láàyè.

17 Nítorí ìlera mi ni mo ṣe ní ìbànújẹ́ lọpọlọpọ;

ìwọ ni o dì mí mú,

tí n kò fi jìn sinu kòtò ìparun,

nítorí o ti sọ gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi di ohun ìgbàgbé.

18 Ibojì kò lè dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ,

bẹ́ẹ̀ ni ikú kò lè yìn ọ́;

kò sí ìrètí mọ́ fún àwọn tí wọ́n ti lọ sinu isà òkú,

wọn kò lè gbẹ́kẹ̀lé òdodo rẹ mọ́.

19 Alààyè, àní alààyè, ni ó lè máa yìn ọ́

bí mo ti yìn ọ́ lónìí.

Baba a máa kọ́ àwọn ọmọ rẹ̀, nípa òdodo rẹ.

20 OLUWA yóo gbà mí là,

a óo fi àwọn ohun èlò orin olókùn kọrin ninu ilé OLUWA,

ní gbogbo ọjọ́ ayé wa.

Categories
AISAYA

AISAYA 39

Ọba Babiloni kọ ìwé kí Hesekaya

1 Ní àkókò náà Merodaki Baladani ọmọ Baladani, ọba Babiloni, fi ìwé ati ẹ̀bùn rán àwọn ikọ̀ kan sí Hesekaya, nítorí ó gbọ́ pé ara rẹ̀ kò ti dá tẹ́lẹ̀ ṣugbọn ara rẹ̀ ti wá le.

2 Hesekaya gbà wọ́n lálejò, ó sì fi àwọn nǹkan tí ó wà ninu ilé ìṣúra rẹ̀ hàn wọ́n, fadaka ati wúrà, àwọn nǹkan olóòórùn dídùn ati òróró olówó iyebíye, ilé ìkó nǹkan ìjà ogun sí, ati gbogbo nǹkan tí ó wà ninu ilé ìṣúra. Kò sí nǹkan tí ó wà ní ìpamọ́ ní ààfin Hesekaya ní ilé rẹ̀ tí kò fihàn wọ́n.

3 Lẹ́yìn náà Aisaya wolii tọ Hesekaya ọba lọ, ó bi í pé, “Kí ni àwọn ọkunrin wọnyi wí, láti ibo ni wọ́n sì ti wá sọ́dọ̀ rẹ?” Hesekaya dáhùn, ó ní, “Láti ilẹ̀ òkèèrè, ní Babiloni ni wọ́n ti wá.”

4 Aisaya tún bi í pé, “Kí ni wọ́n rí láàfin rẹ?” Hesekaya dáhùn, ó ní, “Gbogbo ohun tó wà láàfin ni wọ́n rí. Kò sí ohun tí ó wà ní ilé ìṣúra mi tí n kò fihàn wọ́n.”

5 Aisaya bá sọ fún Hesekaya, pé, “Gbọ́ ohun tí OLUWA àwọn ọmọ ogun wí:

6 Ó ní, ‘Ọjọ́ ń bọ̀ tí a óo ru gbogbo ohun tí ó wà láàfin rẹ lọ sí Babiloni, ati gbogbo ìṣúra tí àwọn baba ńlá rẹ ti kó jọ títí di òní. Kò ní ku nǹkankan.’ OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.

7 ‘A óo kó ninu àwọn ọmọ bíbí inú rẹ lọ, a óo sì fi wọ́n ṣe ìwẹ̀fà láàfin ọba Babiloni.’ ”

8 Hesekaya dá Aisaya lóhùn, ó ní, “Ohun rere ni OLUWA sọ.” Ó sọ bẹ́ẹ̀ nítorí ó rò pé alaafia ati ìfọ̀kànbalẹ̀ yóo wà ní àkókò tòun.