Categories
AISAYA

AISAYA 10

1 Àwọn tí ń ṣe òfin tí kò tọ́ gbé!

Bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn akọ̀wé, tí ń kọ̀wé láti ni eniyan lára;

2 wọ́n ń dínà ìdájọ́ òdodo fún àwọn aláìní,

wọn kò sì jẹ́ kí àwọn talaka ààrin àwọn eniyan mi rí ẹ̀tọ́ wọn gbà,

kí wọ́n lè sọ àwọn opó di ìkógun.

3 Kí ni ẹ óo ṣe lọ́jọ́ ìjìyà yín

tí ìparun bá dé láti òkèèrè?

Ta ni ẹ óo sá tọ̀ lọ fún ìrànlọ́wọ́?

Níbo ni ẹ óo kó ọrọ̀ yín sí?

4 Kò sí ohun tí ó kù àfi kí ẹ kú lójú ogun,

tabi kí ẹ ká góńgó láàrin àwọn tí wọ́n kó lẹ́rú.

Sibẹsibẹ inú OLUWA kò ní rọ̀,

bẹ́ẹ̀ ni kò ní dá ọwọ́ ìjà rẹ̀ dúró.

Asiria ṣe Àṣejù

5 Háà! Asiria!

Orílẹ̀-èdè tí mò ń lò bíi kùmọ̀, ati bíi ọ̀pá

nígbà tí inú bá bí mi.

6 Mo rán wọn láti gbógun ti àwọn tí kò mọ Ọlọrun,

ati àwọn eniyan tí wọ́n bá mú mi bínú.

Pé kí wọ́n kó wọn lẹ́rù.

Kí wọ́n kó wọn lẹ́rú

kí wọ́n tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀ bíi ẹrọ̀fọ̀

tí à ń tẹ̀ mọ́lẹ̀ níta gbangba.

7 Ṣugbọn ọba Asiria kò pa irú ète yìí,

kò sì ní irú èrò yìí lọ́kàn;

gbogbo èrò ọkàn rẹ̀ ni láti pa ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè run

8 nítorí ó wí pé:

“Ṣebí ọba ni gbogbo àwọn olórí ogun mi!

9 Ṣebí bíi Kakemiṣi ni Kalino rí,

tí Hamati rí bíi Aripadi,

tí Samaria kò sì yàtọ̀ sí Damasku?

10 Bí ọwọ́ mi ṣe tẹ àwọn ìlú àwọn abọ̀rìṣà,

tí oriṣa wọn lágbára ju ti Jerusalẹmu ati Samaria lọ,

11 ṣé n kò ní lè ṣe sí Jerusalẹmu ati àwọn oriṣa rẹ̀

bí mo ti ṣe Samaria ati àwọn oriṣa rẹ̀?”

12 Nígbà tí OLUWA bá parí bírà tí ó ń dá ní òkè Sioni ati ní Jerusalẹmu,

yóo fìyà jẹ ọba Asiria fún ìwà ìgbéraga ati àṣejù rẹ̀.

13 Nítorí ó ní,

“Agbára mi ni mo fi ṣe èyí,

ọgbọ́n mi ni mo fi ṣe é

nítorí pé mo jẹ́ amòye.

Mo yí ààlà àwọn orílẹ̀-èdè pada,

mo kó ẹrù tí ó wà ninu ilé ìṣúra wọn.

Mo ré àwọn tí wọ́n jókòó lórí ìtẹ́ bọ́ sílẹ̀ bí alágbára ọkunrin.

14 Mo nawọ́ kó ọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè,

bí ẹni nawọ́ kó ọmọ ẹyẹ.

Mo kó gbogbo ayé,

bí ẹni kó ẹyin ẹyẹ tí ó kọ ẹyin rẹ̀ sílẹ̀, tí ó fò lọ,

kò sí ẹnìkan tí ó lè ṣe nǹkankan,

kò sí ẹnìkan tí ó lanu sọ̀rọ̀,

bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò gbin.”

15 Ǹjẹ́ fáàrí àáké lè pọ̀ ju ti ẹni tí ó ń fi gégi lọ?

Tabi ayùn lè fọ́nnu sí ẹni tí ó ń fi rẹ́ igi?

Ǹjẹ́ kùmọ̀ lè mú ẹni tí ó ń lò ó lọ́wọ́,

tabi kí ọ̀pá mú ẹni tí ó ni í lọ́wọ́?

16 Nítorí náà, OLUWA àwọn ọmọ ogun yóo rán àìsàn apanirun

sí ààrin àwọn akọni ọmọ ogun rẹ̀.

Dípò ohun tí wọ́n fi ń ṣe ògo,

ajónirun yóo jó wọn bí ìgbà tí iná bá jóni.

17 Ìmọ́lẹ̀ Israẹli yóo di iná,

Ẹni Mímọ́ rẹ̀ yóo di ahọ́n iná;

yóo sì jó àwọn ẹ̀gún wẹ́wẹ́ ati ẹ̀gún ọ̀gàn rẹ̀ run ní ọjọ́ kan.

18 OLUWA yóo pa àwọn igi ńlá inú igbó rẹ̀ run,

yóo pa àwọn igi eléso ilẹ̀ rẹ́ tèsotèso,

bí ìgbà tí àrùn bá gbẹ eniyan.

19 Ohun tí yóo kù ninu àwọn igi igbó rẹ̀

kò ní ju ohun tí ọmọde lè kà, kí ó sì kọ sílẹ̀ lọ.

Àwọn Díẹ̀ Yóo Pada Wá

20 Ní ọjọ́ náà, ìyókù Israẹli ati àwọn tí yóo yè ní agbo ilé Jakọbu, kò ní gbé ara lé ẹni tí ó ṣá wọn lọ́gbẹ́ mọ́, ṣugbọn OLUWA, Ẹni Mímọ́ Israẹli ni wọn óo fẹ̀yìn tì ní òtítọ́.

21 Àwọn yòókù yóo pada, àwọn yòókù Jakọbu yóo pada sọ́dọ̀ Ọlọrun alágbára.

22 Israẹli, bí àwọn eniyan rẹ tilẹ̀ pọ̀ bí iyanrìn etí òkun, díẹ̀ ninu wọn ni yóo pada, nítorí ìparun ti di òfin ó sì kún fún òdodo

23 Nítorí OLUWA, OLUWA, àwọn ọmọ ogun yóo ṣe iṣẹ́ rẹ̀ ní àṣeparí láàrin gbogbo ayé gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe é lófin.

OLUWA Yóo Jẹ Asiria Níyà

24 Nítorí náà OLUWA, OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, “Ẹ̀yin eniyan mi tí ń gbé Sioni, Ẹ má bẹ̀rù àwọn ará Asiria bí wọn bá fi ọ̀gọ lù yín, tabi tí wọn gbé ọ̀pá sókè si yín bí àwọn ará Ijipti ti ṣe si yín.

25 Nítorí pé láìpẹ́, ibinu mi si yín yóo kásẹ̀ nílẹ̀, n óo sì dojú ibinu mi kọ wọ́n láti pa wọ́n run.

26 Èmi, OLUWA àwọn ọmọ ogun, n óo fi ọ̀pá mi nà wọ́n, bí ìgbà tí mo na àwọn ará Midiani ní ibi àpáta Orebu. Ọ̀pá rẹ̀ yóo wà lórí òkun. Yóo tún gbé e sókè bí ó ti ṣe ní Ijipti.

27 Ní ọjọ́ náà, a óo gbé ẹrù tí ó dì lé ọ lórí kúrò, a óo sì fa àjàgà rẹ̀ dá kúrò lọ́rùn rẹ.”

Ọ̀tá Kọlu Jerusalẹmu

28 Ó ti kúrò ní agbègbè Rimoni,

ó ti dé sí Aiati;

ó kọjá ní Migironi,

ó kó ẹrù ogun rẹ̀ jọ sí Mikimaṣi.

29 Wọ́n sọdá sí òdìkejì odò

wọ́n sùn ní Geba di ọjọ́ keji.

Àwọn ará Rama ń wárìrì,

àwọn ará Gibea, ìlú Saulu sá lọ.

30 Kígbe! Ìwọ ọmọbinrin Galimu.

Fetí sílẹ̀ ìwọ Laiṣa,

kí Anatoti sì dá a lóhùn.

31 Madimena ń sá lọ,

àwọn ará Gebimu ń sá àsálà.

32 Ní òní olónìí, yóo dúró ní Nobu,

yóo di ọwọ́ rẹ̀ sí àwọn òkè Sioni,

àní òkè Jerusalẹmu.

33 Ẹ wò ó! OLUWA, OLUWA àwọn ọmọ ogun,

yóo gé àwọn ẹ̀ka igi náà pẹlu agbára tí ó bani lẹ́rù.

Yóo gé àwọn tí ó ga fíofío lulẹ̀,

yóo sì rẹ àwọn agbéraga sílẹ̀.

34 Yóo fi àáké gé àwọn igi igbó tí ó dí,

Lẹbanoni pẹlu gbogbo igi ńláńlá rẹ̀ yóo sì wó.

Categories
AISAYA

AISAYA 11

Ìjọba Tí Ó Tòrò

1 Èèhù kan yóo sọ jáde láti inú kùkùté igi Jese,

ẹ̀ka kan yóo sì yọ jáde láti inú àwọn gbòǹgbò rẹ̀.

2 Ẹ̀mí OLUWA yóo bà lé e,

ẹ̀mí ọgbọ́n ati òye,

ẹ̀mí ìmọ̀ràn ati agbára,

ẹ̀mí ìmọ̀ ati ìbẹ̀rù OLUWA.

3 Ìbẹ̀rù OLUWA ni yóo jẹ́ ìdùnnú rẹ̀

kì í ṣe ohun tí ó fojú rí,

tabi èyí tí ó fi etí gbọ́ ni yóo fi ṣe ìdájọ́.

4 Ṣugbọn yóo fi òdodo ṣe ìdájọ́ àwọn talaka,

yóo fi ẹ̀tọ́ gbèjà àwọn onírẹ̀lẹ̀,

yóo fi ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ na ayé bíi pàṣán,

yóo sì fi èémí ẹnu rẹ̀ pa àwọn oníṣẹ́ ibi.

5 Òdodo ni yóo fi ṣe àmùrè ìgbàdí rẹ̀,

yóo sì fi òtítọ́ ṣe àmùrè ìgbànú rẹ̀.

6 Ìkookò yóo máa bá ọ̀dọ́ aguntan gbé,

àmọ̀tẹ́kùn yóo sùn sílẹ̀ pẹlu ọmọ ewúrẹ́,

ọmọ mààlúù, ati kinniun, ati ẹgbọ̀rọ̀ ẹran àbọ́pa yóo jọ máa gbé pọ̀,

ọmọ kékeré yóo sì máa kó wọn jẹ.

7 Mààlúù ati ẹranko beari yóo jọ máa jẹun pọ̀,

àwọn ọmọ wọn yóo jọ máa sùn pọ̀,

kinniun yóo sì máa jẹ koríko bí akọ mààlúù.

8 Ọmọ ọmú yóo máa ṣeré lórí ihò paramọ́lẹ̀,

ọmọ tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ já lẹ́nu ọmú

yóo máa fi ọwọ́ bọ inú ihò ejò.

9 Wọn kò ní ṣe eniyan ní jamba mọ́,

tabi kí wọ́n bu eniyan jẹ ní gbogbo orí òkè mímọ́ mi.

Nítorí ìmọ̀ OLUWA yóo kún gbogbo ayé

bí omi ṣe kún gbogbo inú òkun.

Àwọn Ìgbèkùn Yóo Pada

10 Ní ọjọ́ náà, gbòǹgbò Jese yóo dúró bí àsíá fún àwọn orílẹ̀-èdè, òun ni àwọn orílẹ̀-èdè yóo máa wá. Ibùgbé rẹ̀ yóo jẹ́ èyí tí ó lógo.

11 Ní ọjọ́ náà, OLUWA yóo na ọwọ́ rẹ̀ lẹẹkeji, yóo ra àwọn eniyan rẹ̀ yòókù pada ní oko ẹrú, láti Asiria, ati Ijipti, láti Patosi ati Etiopia, láti Elamu ati Ṣinari, láti Amati ati àwọn erékùṣù òkun.

12 Yóo gbé àsíá sókè fún àwọn orílẹ̀-èdè,

yóo kó àwọn Israẹli tí a ti patì jọ.

Yóo ṣa àwọn ọmọ Juda tí wọ́n fọ́nká jọ,

láti orígun mẹrẹẹrin ilẹ̀ ayé.

13 Owú jíjẹ Efuraimu yóo kúrò,

a óo sì pa àwọn tí ń ni Juda lára run.

Efuraimu kò gbọdọ̀ jowú Juda mọ́,

bẹ́ẹ̀ ni Juda kò gbọdọ̀ ni Efuraimu lára mọ.

14 Wọn óo kọlu àwọn ará Filistini ní ìhà ìwọ̀ oòrùn,

wọn yóo jọ ṣẹgun àwọn ará ìlà oòrùn.

Wọn yóo sì jọ dojú ìjà kọ Edomu ati Moabu.

Àwọn ará Amoni yóo gbọ́ràn sí wọn lẹ́nu.

15 OLUWA yóo pa Ijipti run patapata.

Yóo na ọwọ́ ìjì líle sí orí odò Pirati,

yóo sì pín in sí ọ̀nà meje,

kí àwọn eniyan lè máa ríbi là á kọjá.

16 Ọ̀nà tí ó gbòòrò yóo wà láti Asiria, fún ìyókù àwọn eniyan rẹ̀;

bí ó ti ṣe wà fún àwọn ọmọ Israẹli,

nígbà tí wọn ń bọ̀ láti Ijipti.

Categories
AISAYA

AISAYA 12

Orin Ọpẹ́

1 O óo sọ ní ọjọ́ náà pé,

“N óo fi ọpẹ́ fún OLUWA,

nítorí pé bí ó tilẹ̀ bínú sí mi,

inú rẹ̀ ti rọ̀, ó sì tù mí ninu.

2 Wò ó! Ọlọrun ni olùgbàlà mi,

n óo gbẹ́kẹ̀lé e

ẹ̀rù kò sì ní bà mí,

nítorí pé OLUWA Ọlọrun ni agbára mi, ati orin mi,

òun sì ni Olùgbàlà mi.”

3 Tayọ̀tayọ̀ ni ẹ óo fi máa rí ìgbàlà

bí ẹni pọn omi láti inú kànga.

4 Ẹ óo sọ ní ọjọ́ náà pé,

“Ẹ fọpẹ́ fún OLUWA,

ẹ ké pe orúkọ rẹ̀,

ẹ kéde iṣẹ́ rere rẹ̀ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè;

ẹ kéde pé a gbé orúkọ rẹ̀ ga.

5 Ẹ kọ orin ìyìn sí OLUWA

nítorí ó ṣe nǹkan tí ó lógo,

jẹ́ kí èyí di mímọ̀ ní gbogbo ayé.

6 Ẹ̀yin tí ń gbé Sioni,

ẹ hó, ẹ kọrin ayọ̀, ẹ̀yin olùgbé Sioni,

nítorí Ẹni ńlá ni Ẹni Mímọ́ Israẹli

tí ó wà láàrin yín.”

Categories
AISAYA

AISAYA 13

Ọlọrun Yóo Jẹ Babiloni Níyà

1 Ìran tí Aisaya ọmọ Amosi rí sí Babiloni:

2 Ẹ ta àsíá ní orí òkè gíga,

ẹ gbóhùn sókè sí wọn.

Ẹ juwọ́, kí àwọn ológun gba ẹnu ibodè àwọn ọlọ́lá wọlé.

3 Èmi pàápàá ti pàṣẹ fún àwọn tí mo yà sọ́tọ̀,

mo ti pe àwọn akọni mi, tí mo fi ń yangàn,

láti fi ibinu mi hàn.

4 Gbọ́ ariwo lórí òkè, bí ohùn ọ̀pọ̀ eniyan,

gbọ́ ariwo ìdàrúdàpọ̀ ìjọba àwọn orílẹ̀-èdè tí ó ń péjọ pọ̀!

OLUWA àwọn ọmọ ogun

ní ń kó àwọn ọmọ ogun jọ fún ogun.

5 Wọ́n wá láti ilẹ̀ òkèèrè,

láti ìpẹ̀kun ayé.

OLUWA ń bọ̀ pẹlu àwọn ohun ìjà ibinu rẹ̀,

tí yóo fi pa gbogbo ayé run.

6 Ẹ pohùnréré ẹkún,

nítorí pé ọjọ́ OLUWA súnmọ́lé,

yóo dé bí ìparun láti ọwọ́ Olodumare.

7 Nítorí náà ọwọ́ gbogbo eniyan yóo rọ,

ọkàn gbogbo eniyan yóo rẹ̀wẹ̀sì;

8 ẹnu yóo sì yà wọ́n.

Ìpayà ati ìrora yóo mú wọn,

wọn yóo wà ninu ìrora bí obinrin tí ó ń rọbí;

wọn óo wo ara wọn tìyanu-tìyanu,

ojú yóo sì tì wọ́n.

9 Wò ó! Ọjọ́ OLUWA dé tán,

tìkàtìkà pẹlu ìrúnú ati ibinu gbígbóná láti sọ ayé di ahoro,

ati láti pa àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ inú rẹ̀ run.

10 Nítorí àgbájọpọ̀ àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run

yóo kọ̀, wọn kò ní tan ìmọ́lẹ̀.

Oòrùn yóo ṣókùnkùn nígbà tí ó bá yọ,

òṣùpá kò sì ní tan ìmọ́lẹ̀.

11 N óo fìyà jẹ ayé nítorí iṣẹ́ ibi rẹ̀,

n óo sì jẹ àwọn ìkà níyà nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

N óo fòpin sí àṣejù àwọn onigbeeraga,

n óo rẹ ìgbéraga àwọn tí kò lójú àánú sílẹ̀.

12 N óo sọ eniyan di ohun tí ó ṣọ̀wọ́n ju wúrà dáradára lọ,

irú eniyan yóo ṣọ̀wọ́n ju wúrà ilẹ̀ Ofiri lọ.

13 Nítorí náà n óo mú kí àwọn ọ̀run wárìrì

ayé yóo sì mì tìtì tóbẹ́ẹ̀ tí yóo sún kúrò ní ipò rẹ̀,

nítorí ibinu OLUWA àwọn ọmọ ogun ní ọjọ́ tí inú rẹ̀ bá ru.

14 Eniyan yóo dàbí àgbọ̀nrín tí ọdẹ ń lé,

ati bí aguntan tí kò ní olùṣọ́;

olukuluku yóo doríkọ ọ̀dọ̀ àwọn eniyan rẹ̀,

wọn óo sì sá lọ sí ilẹ̀ wọn.

15 Ẹnikẹ́ni tí wọ́n bá rí, wọn óo fi ọ̀kọ̀ gún un pa,

ẹni tí ọwọ́ bá tẹ̀, idà ni wọ́n ó fi pa á.

16 A óo so àwọn ọmọ wọn mọ́lẹ̀ lójú wọn,

a óo kó ilé wọn,

a óo sì bá àwọn obinrin wọn lòpọ̀ pẹlu agbára.

17 Wò ó! N óo rú àwọn ará Media sókè sí wọn,

àwọn tí wọn kò bìkítà fún fadaka

bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ka wúrà sí.

Wọn óo wá bá Babiloni jà.

18 Wọn yóo fi ọfà pa àwọn ọdọmọkunrin,

wọn kò ní ṣàánú oyún inú,

bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní ṣàánú àwọn ọmọde.

19 Babiloni, ìwọ tí o lógo jù láàrin gbogbo ìjọba ayé,

ìwọ tí o jẹ́ ẹwà ati ògo àwọn ará Kalidea,

yóo dàbí Sodomu ati Gomora,

nígbà tí Ọlọrun pa wọ́n run.

20 Ẹnikẹ́ni kò ní gbé ibẹ̀ láti ìran dé ìran,

àwọn ará Arabia kankan kò ní pa àgọ́ sibẹ,

bẹ́ẹ̀ ni àwọn darandaran kankan kò ní jẹ́ kí agbo aguntan wọn sinmi níbẹ̀.

21 Ṣugbọn àwọn ẹranko ní yóo máa sùn níbẹ̀

ilé rẹ̀ yóo sì kún fún ẹyẹ òwìwí,

ògòǹgò yóo máa gbè ibẹ̀

ẹhànnà òbúkọ yóo sì máa ta pọ́núnpọ́nún káàkiri ibẹ̀.

22 Àwọn ìkookò yóo máa ké ninu ilé ìṣọ́ rẹ̀,

ààfin rẹ̀ yóo di ibùgbé àwọn ajáko,

àkókò rẹ̀ súnmọ́ etílé,

ọjọ́ rẹ̀ kò sì ní pẹ́ mọ́.

Categories
AISAYA

AISAYA 14

Ìpadàbọ̀ láti Ìgbèkùn

1 OLUWA yóo ṣíjú àánú wo Jakọbu yóo tún yan Israẹli, yóo sì fi wọ́n sórí ilẹ̀ wọn. Àwọn àlejò yóo darapọ̀ mọ́ wọn, wọn yóo sì di ọ̀kan náà pẹlu ilé Jakọbu.

2 Àwọn orílẹ̀-èdè yóo ràn wọ́n lọ́wọ́ láti pada sí ilẹ̀ wọn, àwọn orílẹ̀-èdè wọnyi yóo sì di ẹrú fún àwọn ọmọ Israẹli. Wọn yóo pada sọ àwọn tí ó kó wọn lẹ́rú di ẹrú, wọn yóo sì jọba lórí àwọn tí ó ni wọ́n lára.

Ọba Babiloni ní Isà Òkú

3 Nígbà tí OLUWA bá fun yín ní ìsinmi kúrò ninu làálàá ati rògbòdìyàn ati iṣẹ́ àṣekára tí wọn ń fi tipá mu yín ṣe,

4 ẹ óo kọrin òwe bú ọba Babiloni pé:

“Agbára aninilára ti pin

ìpayà ojoojumọ ti dópin.

5 OLUWA ti ṣẹ́ ọ̀pá àṣẹ àwọn ẹni ibi,

ati ọ̀pá àṣẹ àwọn olórí

6 tí wọn ń fi ibinu lu àwọn eniyan láì dáwọ́ dúró,

tí wọn ń fi ibinu ṣe àkóso àwọn orílẹ̀-èdè,

tí ó ń ṣe inúnibíni lemọ́lemọ́.

7 Gbogbo ayé wà ní ìsinmi ati alaafia

wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kọ orin ayọ̀.

8 Àwọn igi Sipirẹsi ń yọ̀ yín;

àwọn igi Kedari ti Lẹbanoni sì ń sọ pé,

‘Láti ìgbà tí a ti rẹ ọba Babiloni sílẹ̀,

kò sí agégi kan tí ó wá dààmú wa mọ́.’

9 “Isà òkú ti lanu sílẹ̀ láti pàdé rẹ bí o bá ti ń dé.

Ó ta àwọn òkú ọ̀run jí láti kí ọ,

àwọn tí wọ́n ṣe pataki ní àkókò wọn,

Ó gbé gbogbo àwọn ọba orílẹ̀-èdè dìde lórí ìtẹ́ wọn.

10 Gbogbo wọn yóo wí fún ọ pé,

‘Àárẹ̀ ti mu yín gẹ́gẹ́ bí ó ti mú àwa náà.

Ẹ ti dàbí i wa.

11 A ti fa ògo yín ati ohùn hapu yín sinu isà òkú.

Ìdin di ibùsùn tí ẹ sùn lé lórí

àwọn kòkòrò ni ẹ sì fi bora bí aṣọ.’

12 “Ọba Babiloni, wò ó! Bí o ti jábọ́ láti ojú ọ̀run,

ìwọ tí o dàbí ìràwọ̀ òwúrọ̀!

Wò ó bí a ti sọ ọ́ di ẹni ilẹ̀,

ìwọ tí o ti pa ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè run rí.

13 Ó pinnu lọ́kàn ara rẹ̀ pé,

‘N óo gòkè dé ọ̀run,

n óo gbé ìtẹ́ mi kọjá àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run;

n óo jókòó lórí òkè àpéjọ àwọn eniyan,

ní ìhà àríwá ní ọ̀nà jíjìn réré.

14 N óo gòkè kọjá ìkùukùu ojú ọ̀run,

n óo wá dàbí Olodumare.’

15 Ṣugbọn a já ọ lulẹ̀ sinu isà òkú,

sí ìsàlẹ̀ ọ̀gbun.

16 “Ẹnikẹ́ni tí ó bá rí ọ yóo tẹjú mọ́ ọ,

wọ́n óo fi ọ́ ṣe àríkọ́gbọ́n pé,

‘Ṣé ọkunrin tí ó ń kó ìpayà bá gbogbo ayé nìyí,

tí ó ń mi àwọn orílẹ̀-èdè jìgìjìgì;

17 ẹni tí ó sọ ayé di aṣálẹ̀,

tí ó sì pa àwọn ìlú ńláńlá rẹ̀ run,

ẹni tí kì í dá àwọn tí ó bá wà ní ìgbèkùn rẹ̀ sílẹ̀?’

18 Gbogbo ọba àwọn orílẹ̀-èdè dùbúlẹ̀ ninu ògo wọn

olukuluku ninu ibojì tirẹ̀.

19 Ṣugbọn a lé ìwọ kúrò ninu ibojì rẹ,

bí ọmọ tí a bí kí oṣù rẹ̀ tó pé,

tí a gbé òkú rẹ̀ sọnù;

tí a jù sáàrin òkú àwọn jagunjagun tí a pa lójú ogun;

àwọn tí a jù sinu kòtò olókùúta,

bí àwọn tí a tẹ̀ ní àtẹ̀pa.

20 A kò ní sin ọ́ gẹ́gẹ́ bí àwọn ọba yòókù,

nítorí pé o ti pa ilẹ̀ rẹ run,

o sì ti pa àwọn eniyan rẹ.

Kí á má dárúkọ àwọn ìran ẹni ibi mọ́ títí lae!

21 Ẹ múra láti pa àwọn ọmọ rẹ̀ run

nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba wọn,

kí wọn má baà tún gbógun dìde,

kí wọn gba gbogbo ayé kan,

kí wọn sì kọ́ ọpọlọpọ ìlú sórí ilẹ̀ ayé.”

Ọlọrun Yóo Pa Babiloni Run

22 OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, “N óo gbógun tì wọ́n, n óo pa orúkọ Babiloni rẹ́ ati ìyókù àwọn eniyan tí ó wà ninu rẹ̀, ati arọmọdọmọ wọn.

23 N óo sọ ọ́ di ibùgbé òòrẹ̀, adágún omi yóo wà káàkiri inú rẹ, n óo sì fi ọwọ̀ ìparun gbá a. Èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

Ọlọrun Yóo Pa Àwọn Ará Asiria Run

24 OLUWA àwọn ọmọ ogun ti búra, ó ní,

“Bí mo ti rò ó bẹ́ẹ̀ ni yóo rí;

ohun tí mo pinnu ni yóo sì ṣẹ.

25 Pé n óo pa àwọn ará Asiria run lórí ilẹ̀ mi;

n óo sì fẹsẹ̀ tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀ lórí àwọn òkè mi.

Àjàgà rẹ̀ yóo bọ́ kúrò lọ́rùn àwọn eniyan mi,

ati ẹrù tí ó dì lé wọn lórí.

26 Ohun tí mo ti pinnu nípa gbogbo ayé nìyí,

mo sì ti na ọwọ́ mi sórí orílẹ̀-èdè gbogbo láti jẹ wọ́n níyà.”

27 OLUWA àwọn ọmọ ogun ti pinnu;

ta ni ó lè yí ìpinnu rẹ̀ pada?

Ó ti dáwọ́lé ohun tí ó fẹ́ ṣe

ta ni lè ká a lọ́wọ́ kò?

Ọlọrun Yóo Pa Àwọn Ará Filistini Run

28 Ọ̀rọ̀ OLUWA tí Aisaya sọ ní ọdún tí ọba Ahasi kú:

29 Gbogbo ẹ̀yin ará Filistini,

ẹ má yọ̀ pé a ti ṣẹ́ ọ̀pá tí ó lù yín;

nítorí pé paramọ́lẹ̀ ni yóo yọ jáde láti inú àgékù ejò,

ejò tí ń fò sì ni ọmọ rẹ̀ yóo yà.

30 Àkọ́bí talaka yóo rí oúnjẹ jẹ,

aláìní yóo sì dùbúlẹ̀ láì léwu.

Ṣugbọn n óo fi ìyàn pa àwọn ọmọ ilẹ̀ rẹ,

a óo sì fi idà pa àwọn tó kù ní ilẹ̀ rẹ.

31 Máa sọkún, ìwọ ẹnubodè,

kí ìwọ ìlú sì figbe ta.

Ẹ̀yin ará Filistini, ẹ máa gbọ̀n jìnnìjìnnì

nítorí pé àwọn ọmọ ogun kan ń rọ́ bọ̀ bí èéfín, láti ìhà àríwá,

kò sí ọ̀kan ninu àwọn ọmọ ogun wọn

tí ó ń ṣe dìẹ̀dìẹ̀ bọ̀ lẹ́yìn.

32 Èsì wo ni a óo fún àwọn ikọ̀ orílẹ̀-èdè Filistini?

A óo sọ fún wọn pé,

“OLUWA ti fi ìdí Sioni sọlẹ̀

àwọn tí à ń pọ́n lójú láàrin àwọn eniyan rẹ̀

yóo fi ibẹ̀ ṣe ibi ààbò.”

Categories
AISAYA

AISAYA 15

OLUWA yóo Pa Moabu Run

1 Ọ̀rọ̀ tí OLUWA sọ nípa ilẹ̀ Moabu nìyí:

Nítorí tí a wó ìlú Ari ati Kiri lulẹ̀ ní òru ọjọ́ kan ṣoṣo,

ó parí fún Moabu.

2 Àwọn ọmọbinrin Diboni ti gun àwọn ibi pẹpẹ tí wọ́n ti ń bọ̀rìṣà lọ, wọ́n lọ sọkún.

Moabu ń pohùnréré ẹkún nítorí Nebo ati Medeba.

Gbogbo orí wọn pá, wọ́n sì ti fá gbogbo irùngbọ̀n wọn.

3 Wọ́n da aṣọ ọ̀fọ̀ bora ní ìta gbangba.

Gbogbo wọn dúró lórí òrùlé ilé wọn,

ati ní gbogbo gbàgede, wọ́n ń pohùnréré ẹkún,

omijé sì ń dà lójú wọn.

4 Heṣiboni ati Eleale ń kígbe lóhùn rara,

àwọn ará Jahasi gbọ́ ariwo wọn;

nítorí náà àwọn ọmọ ogun Moabu sọkún,

ọkàn rẹ̀ sì wárìrì.

5 Ọkàn mi sọkún fún Moabu;

àwọn ìsáǹsá rẹ̀ sá lọ sí Soari ati Egilati Ṣeliṣiya.

Ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Luhiti, wọ́n ń sọkún bí wọ́n ti ń gòkè lọ,

wọ́n sì ń kígbe arò bí wọ́n tí ń lọ sí Horonaimu.

6 Àwọn odò Nimrimu di aṣálẹ̀,

koríko ibẹ̀ gbẹ;

àwọn ohun ọ̀gbìn tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń yọ jóná mọ́lẹ̀,

bẹ́ẹ̀ ni ewé kò rú mọ́.

7 Nítorí náà àwọn ohun tí wọ́n ní lọpọlọpọ

ati ohun ìní tí wọn ti kó jọ,

ni wọ́n kó lọ sí ìkọjá odò Wilo.

8 Nítorí ariwo kan ti gba gbogbo ilẹ̀ Moabu kan,

ẹkún náà dé Egilaimu,

ìpohùnréré náà sì dé Beerelimu.

9 Nítorí odò Diboni kún fún ẹ̀jẹ̀,

sibẹsibẹ n óo jẹ́ kí ohun tí ó jù bẹ́ẹ̀ lọ dé bá a.

Kinniun ni yóo pa àwọn ará Moabu tí ó bá ń sá lọ

ati àwọn eniyan tí ó bá kù ní ilẹ̀ náà.

Categories
AISAYA

AISAYA 16

Kò sí Ìrètí fún Moabu Mọ́

1 Wọ́n ti kó àgbò láti Sela, ní ọ̀nà aṣálẹ̀,

wọ́n fi ranṣẹ sí aláṣẹ ilẹ̀ náà, ní òkè Sioni.

2 Àwọn ọmọbinrin Moabu dúró létí odò Anoni,

wọ́n ń rìn síwá, sẹ́yìn,

wọ́n ń lọ sókè, sódò,

bí ọmọ ẹyẹ tí a lé kúrò ninu ìtẹ́.

3 “Gbà wá ní ìmọ̀ràn,

máa ṣe ẹ̀tọ́ fún wa.

Fi òjìji rẹ dáàbò bò wá,

kí ara lè tù wá lọ́sàn-án gangan,

bí ẹni pé alẹ́ ni.

Dáàbò bo àwọn tí a lé jáde;

má tú àṣírí ẹni tí ń sálọ.

4 Jẹ́ kí àwọn tí a lé jáde ní Moabu, máa gbé ààrin yín.

Dáàbò bò wọ́n lọ́wọ́ àwọn apanirun.”

Nígbà tí aninilára kò bá sí mọ́ tí ìparun bá dópin,

tí atẹnimọ́lẹ̀ bá ti kúrò ní ilẹ̀ náà.

5 Nígbà náà a óo fìdí ìtẹ́ múlẹ̀ pẹlu ìfẹ́ tí kì í yẹ̀.

Ẹnìkan tí ń ṣe ìdájọ́ ẹ̀tọ́ ati òdodo yóo jókòó lórí ìtẹ́ náà,

Yóo dúró lórí òtítọ́ ní ìdílé Dafidi.

6 A ti gbọ́ ìròyìn ìgbéraga Moabu,

bí ó ṣe ń ṣe àfojúdi tí ó sì ń sọ ìsọkúsọ:

ṣugbọn lásán ni ìgbéraga rẹ̀.

7 Nítorí náà, kí Moabu máa pohùnréré ẹkún,

kí gbogbo eniyan máa sun ẹkún arò ní Moabu.

Wọn óo sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn,

nígbà tí wọn ba ranti àkàrà Kiri Heresi,

tí ó ní èso àjàrà ninu.

8 Gbogbo oko ni ó rọ ní Heṣiboni;

bẹ́ẹ̀ náà ni ọgbà Sibuma:

àwọn olórí orílẹ̀-èdè ti gé àwọn ẹ̀ka rẹ̀ lulẹ̀,

èyí tí ó tàn kálẹ̀ dé Jaseri títí dé inú aṣálẹ̀.

Ìtàkùn rẹ̀ tàn kálẹ̀,

wọ́n kọjá sí òdìkejì òkun.

9 Nítorí náà mo sọkún fún ọgbà àjàrà Sibuma

bí mo ṣe sọkún fún Jaseri;

mo sì sọkún nítorí Heṣiboni ati Eleale,

mo sọkún, omi ń dà lójú mi pòròpòrò

nítorí gbogbo ìkórè yín, ati èso oko yín ni ogun ti kó lọ.

10 Wọ́n ti kó ayọ̀ ati ìdùnnú lọ kúrò ninu oko eléso;

ẹnikẹ́ni kò kọrin bẹ́ẹ̀ ni kò sí ariwo híhó ninu ọgbà àjàrà wọn.

Kò sí àwọn tí ó ń pọn ọtí ninu rẹ̀ mọ́

bẹ́ẹ̀ ni a kò gbọ́ ariwo àwọn tí ń pọn ọtí mọ́.

11 Nítorí náà, ẹ̀mí mi kọrin arò bíi ti dùùrù fún Moabu,

ọkàn mi kérora, fún Moabu ati Kiri Heresi.

12 Nígbà tí Moabu bá wá siwaju,

tí ó fi gbogbo agbára gbadura ninu ilé oriṣa rẹ̀,

títí ó fi rẹ̀ ẹ́,

adura rẹ̀ kò ní gbà.

13 Ọ̀rọ̀ tí OLUWA ti kọ́ sọ nípa Moabu tẹ́lẹ̀ nìyí.

14 Ṣugbọn nisinsinyii, OLUWA ní, “Nígbà tí a óo fi rí ọdún mẹta, tíí ṣe iye ọdún alágbàṣe, a óo ti sọ ògo Moabu di ilẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé eniyan inú rẹ̀ pọ̀, àwọn díẹ̀ ni yóo ṣẹ́kù, àárẹ̀ yóo sì ti mú wọn.”

Categories
AISAYA

AISAYA 17

Ọlọrun Yóo Jẹ Siria ati Israẹli Níyà

1 Ọ̀rọ̀ OLUWA sí ilẹ̀ Damasku nìyí:

“Damasku kò ní jẹ́ ìlú mọ́

òkítì àlàpà ni yóo dà.

2 Àwọn ìlú rẹ̀ yóo di àkọ̀tì títí lae

wọn yóo di ibùjẹ àwọn ẹran,

níbi tí àwọn ẹran yóo dùbúlẹ̀,

tí ẹnikẹ́ni kò sì ní dẹ́rùbà wọ́n.

3 Ìlú olódi kò ní sí mọ́ ní Efuraimu,

kò sì ní sí ìjọba mọ́ ní Damasku,

àwọn tí wọ́n bá ṣẹ́kù ní Siria

yóo sì dàbí ògo àwọn ọmọ Israẹli,

OLUWA àwọn ọmọ ogun ló sọ bẹ́ẹ̀.

4 “Tó bá di ìgbà náà,

a óo rẹ ògo àwọn ọmọ Israẹli sílẹ̀,

ọrọ̀ wọn yóo di àìní.

5 Yóo dàbí ìgbà tí eniyan kórè ọkà lóko,

tí ó kó ṣiiri ọkà kún apá.

Tí àwọn kan tún wá ṣa ọkà yòókù,

tí àwọn tí wọn kọ́ kórè ọkà gbàgbé ní àfonífojì Refaimu.

6 Àṣàkù yóo kù níbẹ̀,

bí ìgbà tí eniyan gbọn igi olifi,

yóo ku meji tabi mẹta péré ní góńgó orí igi,

tabi bíi mẹrin tabi marun-un lórí ẹ̀ka igi.”

OLUWA Ọlọrun Israẹli ló sọ bẹ́ẹ̀.

7 Tó bá di ìgbà náà, àwọn eniyan yóo bọ̀wọ̀ fún Ẹlẹ́dàá wọn, wọn yóo sì máa wo ojú Ẹni Mímọ́ Israẹli.

8 Wọn kò ní náání pẹpẹ tí wọ́n fọwọ́ ara wọn tẹ́ bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní gbójúlé àwọn ère tí wọ́n fọwọ́ ara wọn ṣe, ìbáà jẹ́ oriṣa Aṣera tabi pẹpẹ turari.

9 Tó bá di ìgbà náà, àwọn ìlú olódi ńláńlá wọn yóo dàbí àwọn ìlú tí àwọn ará Hifi ati àwọn ará Amori sá kúrò níbẹ̀, nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli gbógun tì wọ́n; gbogbo rẹ̀ yóo di ahoro.

10 Nítorí pé ẹ ti gbàgbé Ọlọrun olùgbàlà yín,

ẹ kò ranti Àpáta tí ó jẹ́ ààbò yín.

Nítorí náà bí ẹ tilẹ̀ gbin igi dáradára tí ẹ̀ ń bọ ọ́,

tí ẹ sì gbin òdòdó àjèjì tí ẹ̀ ń sìn ín;

11 wọn ìbáà hù lọ́jọ́ tí ẹ gbìn wọ́n,

kí wọ́n yọ òdòdó ní òwúrọ̀ ọjọ́ tí ẹ lọ́ wọn

sibẹsibẹ kò ní sí ìkórè

ní ọjọ́ ìbànújẹ́ ati ìrora tí kò lóògùn.

A Ṣẹgun Àwọn Ọ̀tá

12 Ẹ gbọ́ ariwo ọ̀pọ̀ eniyan,

wọ́n ń hó bí ìgbì òkun.

Ẹ gbọ́ ìró àwọn orílẹ̀-èdè

wọ́n ń hó bíi ríru omi òkun ńlá.

13 Ìró àwọn orílẹ̀-èdè dàbí ti omi òkun ńlá

ṣugbọn OLUWA yóo bá wọn wí wọn óo sì sá lọ.

Wọn óo dàbí ìràwé tí afẹ́fẹ́ ń gbé lọ lórí òkè,

ati bí eruku tí ìjì líle ń fẹ́ kiri.

14 Ìdágìrì yóo bá wọn ní ìrọ̀lẹ́,

kí ilẹ̀ tó mọ́ wọn kò ní sí mọ́;

bẹ́ẹ̀ ni yóo rí fún àwọn tí wọ́n fogun kó wa,

bẹ́ẹ̀ ni yóo rí fún àwọn tí wọ́n kó wa lẹ́rù lọ.

Categories
AISAYA

AISAYA 18

Ọlọrun yóo Jẹ Sudani Níyà

1 Ó ṣe,

ní òkè àwọn odò kan ní ilẹ̀ Sudani

ibìkan wà tí àwọn ẹyẹ ti ń fò pẹ̀ẹ̀rẹ̀pẹ̀.

2 Ẹni tí ó rán ikọ̀ lọ sí òkè odò Naili,

tí wọ́n fẹní ṣọkọ̀ ojú omi.

Ẹ lọ kíá, ẹ̀yin iranṣẹ ayára-bí-àṣá,

ẹ lọ sọ́dọ̀ orílẹ̀-èdè tí ó lágbára, tí ara wọn ń dán,

àwọn tí àwọn eniyan tí wọ́n súnmọ́ wọn

ati àwọn tí ó jìnnà sí wọn ń bẹ̀rù.

Orílẹ̀-èdè tí ó lágbára, tíí sìí máa ń ṣẹgun ọ̀tá,

àwọn tí odò la ilẹ̀ wọn kọjá.

3 Gbogbo aráyé,

ẹ̀yin tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé,

nígbà tí a bá gbé àsíá sókè lórí àwọn òkè,

ẹ wò ó, nígbà tí a bá fun fèrè ogun, ẹ gbọ́.

4 Nítorí pé OLUWA sọ fún mi pé

òun óo fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ wolẹ̀ láti ibi ibùgbé òun

bí ìmọ́lẹ̀ ní ọ̀sán gangan,

ati bí ìkùukùu ninu ooru ìgbà ìkórè.

5 Nítorí pé kí ó tó di ìgbà ìkórè,

lẹ́yìn tí ìtànná àjàrà bá ti rẹ̀, tí ó di èso,

tí àjàrà bẹ̀rẹ̀ sí gbó, tí ó ń pọ́n bọ̀,

ọ̀tá yóo ti dòjé bọ àwọn ìtàkùn àjàrà,

yóo sì gé gbogbo ẹ̀ka rẹ̀ kúrò.

6 Gbogbo wọn yóo wà nílẹ̀,

wọn yóo di ìjẹ fún àwọn ẹyẹ orí òkè,

ati àwọn ẹranko inú ìgbẹ́.

Àwọn ẹyẹ yóo fi wọ́n ṣe oúnjẹ ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn,

àwọn ẹranko yóo fi wọ́n ṣe oúnjẹ jẹ ní ìgbà òtútù.

7 Ní àkókò náà, àwọn eniyan tí wọ́n ga, tí wọ́n sì ń dán,

tí àwọn tí wọ́n súnmọ́ wọn, ati àwọn tí wọ́n jìnnà sí wọn ń bẹ̀rù,

orílẹ̀-èdè tí ó lágbára, tíí sì í máa ń ṣẹgun ọ̀tá,

tí odò la ilẹ̀ wọn kọjá,

wọn óo mú ẹ̀bùn wá fún OLUWA àwọn ọmọ ogun,

ní orí òkè Sioni, tí àwọn eniyan ń jọ́sìn ní orúkọ OLUWA àwọn ọmọ ogun.

Categories
AISAYA

AISAYA 19

Ọlọrun Yóo Jẹ Ijipti Níyà

1 Àsọtẹ́lẹ̀ nípa Ijipti nìyí:

OLUWA gun ìkùukùu lẹ́ṣin, ó ń yára bọ̀ wá sí Ijipti.

Àwọn oriṣa Ijipti yóo máa gbọ̀n níwájú rẹ̀,

ọkàn àwọn ará Ijipti yóo sì dàrú.

2 N óo dá ìdàrúdàpọ̀ sílẹ̀ láàrin àwọn ará Ijipti,

olukuluku yóo máa bá arakunrin rẹ̀ jà,

àwọn aládùúgbò yóo máa bá ara wọn jà,

ìlú kan yóo gbógun ti ìlú keji,

ìjọba yóo máa dìde sí ara wọn.

3 Ìrẹ̀wẹ̀sì yóo dé bá àwọn ará Ijipti,

n óo sọ ète wọn di òfo.

Wọn yóo lọ máa wádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ àwọn oriṣa ati àwọn aláfọ̀ṣẹ

ati lọ́dọ̀ àwọn abókùúsọ̀rọ̀, ati àwọn oṣó.

4 Ṣugbọn n óo fi Ijipti lé aláìláàánú akóniṣiṣẹ́ kan lọ́wọ́

ìkà kan ni yóo sì jọba lé wọn lórí,

bẹ́ẹ̀ ni Oluwa, OLUWA àwọn ọmọ ogun wí.

5 Omi odò Naili yóo gbẹ,

yóo gbẹ, àgbẹkanlẹ̀.

6 Gbogbo odò wọn yóo máa rùn,

gbogbo àwọn odò tí ó ṣàn wọ odò Naili ní Ijipti,

ni yóo fà, tí yóo sì gbẹ:

Gbogbo koríko odò yóo rà.

7 Etí odò Naili yóo di aṣálẹ̀,

gbogbo ohun tí wọ́n bá gbìn sibẹ yóo gbẹ,

ẹ̀fúùfù óo sì gbá wọn dànù.

8 Àwọn apẹja tí ń fi ìwọ̀ ninu odò Naili

yóo ṣọ̀fọ̀,

wọn óo sì sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn;

àwọn tí ń fi àwọ̀n pẹja yóo kérora.

9 Ìdààmú yóo bá àwọn tí ó ń hun aṣọ funfun,

ati àwọn ahunṣọ tí ń lo òwú funfun.

10 Àwọn eniyan pataki ilẹ̀ náà yóo di ẹni ilẹ̀,

ìbànújẹ́ yóo sì bá àwọn alágbàṣe.

11 Òmùgọ̀ ni àwọn olórí wọn ní Soani;

ìmọ̀ràn wèrè sì ni àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n ìgbìmọ̀ Farao ń fún eniyan.

Báwo ni eniyan ṣe lè sọ fún Farao pé,

“Ọmọ Ọlọ́gbọ́n eniyan ni mí,

ọmọ àwọn ọba àtijọ́.”

12 Àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n rẹ dà?

Níbo ni wọ́n wà kí wọ́n sọ fún ọ,

kí wọ́n sì fi ohun tí OLUWA àwọn ọmọ ogun pinnu láti ṣe sí Ijipti hàn ọ́.

13 Àwọn olórí wọn ní Soani ti di òmùgọ̀,

àwọn olórí wọn ní Memfisi sì ti gba ẹ̀tàn;

àwọn tí wọ́n jẹ́ òpómúléró ní ilẹ̀ Ijipti ti ṣi Ijipti lọ́nà.

14 OLUWA ti dá èdè-àìyedè sílẹ̀ láàrin wọn,

wọ́n sì ti ṣi Ijipti lọ́nà ninu gbogbo ìṣe rẹ̀,

bí ìgbà tí ọ̀mùtí bá ń ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n ninu èébì rẹ̀.

15 Kò sí nǹkankan tí ẹnìkan lè ṣe fún Ijipti,

kì báà jẹ́ ọlọ́lá tabi mẹ̀kúnnù,

kì báà jẹ́ eniyan pataki tabi ẹni tí kò jẹ́ nǹkan.

Ijipti Yóo Sin OLUWA

16 Tí ó bá di ìgbà náà, àwọn ará Ijipti yóo di obinrin. Wọn yóo máa gbọ̀n, fún ẹ̀rù, nígbà tí OLUWA àwọn ọmọ ogun bá gbá wọn mú.

17 Ilẹ̀ Juda yóo di ẹ̀rù fún àwọn ará Ijipti, ẹnikẹ́ni tí ó bá gbọ́ yóo bẹ̀rù nítorí ohun tí OLUWA àwọn ọmọ ogun ti pinnu láti ṣe sí Ijipti.

18 Tó bá di ìgbà náà, ìlú marun-un yóo wà ní ilẹ̀ Ijipti, tí wọn yóo máa sọ èdè Kenaani; wọ́n óo búra láti jẹ́ ti OLUWA àwọn ọmọ ogun.

Orúkọ ọ̀kan ninu wọn yóo máa jẹ́ ìlú Oòrùn.

19 Tó bá di ìgbà náà, wọn yóo tẹ́ pẹpẹ kan fún OLUWA láàrin ilẹ̀ Ijipti, ọ̀wọ̀n OLUWA kan yóo sì wà lẹ́gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ ààlà ilẹ̀ rẹ̀.

20 Yóo jẹ́ àmì ati ẹ̀rí fún OLUWA àwọn ọmọ ogun ní ilẹ̀ Ijipti. Nígbà tí wọ́n bá ké pe OLUWA nítorí àwọn aninilára, OLUWA yóo rán olùgbàlà tí yóo gbà wọ́n sí wọn.

21 OLUWA yóo sọ ara rẹ̀ di mímọ̀ fún àwọn ará Ijipti, wọn óo sì mọ OLUWA nígbà náà. Wọ́n yóo máa sin OLUWA pẹlu ẹbọ ati ẹbọ sísun; wọn óo jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún OLUWA, wọn yóo sì mú ẹ̀jẹ́ náà ṣẹ.

22 OLUWA yóo fìyà jẹ àwọn ará Ijipti ṣugbọn yóo wò wọ́n sàn, wọn yóo pada sọ́dọ̀ OLUWA, yóo gbọ́ adura wọn, yóo sì wò wọ́n sàn.

23 Tó bá di ìgbà náà, ọ̀nà tí ó tóbi kan yóo wà láti Ijipti dé Asiria–àwọn ará Asiria yóo máa lọ sí Ijipti, àwọn ará Ijipti yóo sì máa lọ sí Asiria; àwọn ará Ijipti yóo máa jọ́sìn pẹlu àwọn ará Asiria.

24 Ní àkókò náà, Israẹli yóo ṣìkẹta Ijipti ati Asiria, wọn yóo sì jẹ́ ibukun lórí ilẹ̀ fún àwọn ará Ijipti, àwọn eniyan mi.

25 Tí OLUWA àwọn ọmọ ogun ti súre fún pé, “Ibukun ni fún Ijipti, àwọn eniyan mi, ati fún Asiria tí mo fi ọwọ́ mi dá, ati fún Israẹli ìní mi.”