Categories
AISAYA

AISAYA Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Aisaya tí a fi orúkọ rẹ̀ pe ìwé yìí jẹ́ wolii pataki kan, tí ó wà ní Jerusalẹmu ní nǹkan bíi ẹgbẹrin ọdún ó dín díẹ̀ kí á tó bí OLUWA wa (8th Century B.C.) Ọ̀nà mẹta pataki ni a lè pín ìwé yìí sí:

(1) Orí 1–39 Ìtàn nípa ìgbà tí àwọn ará Asiria gbógun ti Juda. Ó hàn sí Aisaya pé kì í ṣe pé àwọn ará Asiria ní agbára láti kojú Juda, ṣugbọn orílẹ̀-èdè Juda ti dẹ́ṣẹ̀: wọn kò pa òfin Ọlọrun mọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò gbẹ́kẹ̀lé e. Láìfi dúdú pe funfun, Aisaya wolii pe àwọn ará Juda ati àwọn olórí wọn pada sí ìlànà Ọlọrun, Ó ní kí wọ́n máa rìn ní ọ̀nà òdodo ati òtítọ́. Ó kìlọ̀ fún wọn pé bí wọn kò bá tẹ̀lé ọ̀rọ̀ Ọlọrun, wọn óo di ẹni ẹ̀kọ̀ wọn óo sì parun. Aisaya sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa alaafia tí yóo kárí ayé, ati nípa ìbí ọba tí ó ṣe pataki jùlọ, tí a óo bí ninu ìran Dafidi.

(2) Orí 40–55 sọ nípa ìtàn ìgbà tí àwọn Juda wà ní oko ẹrú Babiloni, ìyà jẹ wọ́n, wọ́n sì ti sọ̀rètí nù, ṣugbọn Aisaya Wolii kéde pé Ọlọrun yóo dá wọn sílẹ̀ lóko ẹrú, wọn yóo sì pada sí Jerusalẹmu láti bẹ̀rẹ̀ ìgbé ayé tuntun. Kókó tí ó ṣe pataki jù ninu ìpín yìí ni pé Ọlọrun ni OLUWA tí ń ṣe àkóso àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ayé. Lára àwọn ìlànà tí ó ń ṣe fún àwọn eniyan rẹ̀ ni pé kí wọ́n tan ìyìn rere káàkiri gbogbo orílẹ̀-èdè ayé ati pé nípasẹ̀ Israẹli ni àwọn orílẹ̀-èdè náà yóo sì ti rí ibukun gbà. Àwọn ẹsẹ tí wọ́n sọ nípa “Iranṣẹ OLUWA” ninu ìwé yìí wà lára àwọn ẹsẹ tí ọ̀pọ̀ eniyan mọ̀ jù, ninu Majẹmu Laelae.

(3) Orí 56-66 jẹ́ ọ̀rọ̀ ìdánilọ́kànle fún àwọn tí wọ́n pada sí Jerusalẹmu, láti oko ẹrú ní Babiloni, pé Ọlọrun yóo mú gbogbo ìlérí rẹ̀ ṣẹ fún àwọn ará Juda. Wọ́n pe akiyesi sí ṣíṣe pataki ìwà òtítọ́ ati ìdájọ́ òdodo, ati pípa ọjọ́ ìsinmi mọ́, ati ẹbọ rírú ati adura. Jesu lo ọ̀rọ̀ inú 61:1-2 ní ìbẹ̀rẹ̀ ìyìn rere rẹ̀, láti fihàn pé OLUWA ni ó rán òun ní iṣẹ́ ìyìn rere tí òun ń ṣe.

Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí

Àwọn ìkìlọ̀ ati ìlérí 1:1–12:6

Ìjìyà àwọn orílẹ̀-èdè 13:1–23:18

Ìdájọ́ Ọlọrun fún gbogbo ayé 24:1–27:13

Àwọn ìkìlọ̀ ati ìlérí mìíràn 28:1–35:10

Hesekaya ọba Juda ati àwọn ará Asiria 36:1–39:8

Ọ̀rọ̀ ìlérí ati ti ìrètí 40:1–55:13

Àwọn ìkìlọ̀ ati ìlérí 56:1–66:24

Categories
AISAYA

AISAYA 1

1 Ìran tí Aisaya ọmọ Amosi rí sí Juda ati Jerusalẹmu nìyí, nígbà ayé Usaya, Jotamu, Ahasi, ati Hesekaya, àwọn ọba Juda.

OLUWA Bá Àwọn Eniyan Rẹ̀ Wí

2 Máa gbọ́, ìwọ ọ̀run,

sì fetí sílẹ̀, ìwọ ayé

Nítorí pé OLUWA ń sọ̀rọ̀

Ó ní, “Lẹ́yìn tí mo bọ́ àwọn ọmọ,

tí mo tọ́ wọn dàgbà tán,

ọ̀tẹ̀ ni wọ́n dì sí mi.

3 Mààlúù mọ olówó rẹ̀;

kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ sí mọ ibùjẹ tí oluwa rẹ̀ ṣe fún un;

ṣugbọn Israẹli kò mọ nǹkan,

òye kò yé àwọn eniyan mi.”

4 Háà! Orílẹ̀-èdè tí ó kún fún ẹ̀ṣẹ̀,

àwọn eniyan tí ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ ń pa lọ,

ìran oníṣẹ́ ibi;

àwọn ọmọ tí ó kún fún ìwà ìbàjẹ́!

Wọ́n ti kọ OLUWA sílẹ̀,

wọn kò náání Ẹni Mímọ́ Israẹli

wọ́n sì ti kẹ̀yìn sí i.

5 Ṣé ẹ fẹ́ kí á tún jẹ yín níyà sí i ni,

àbí kí ló dé tí ẹ kò fi jáwọ́ ninu ìwà ọ̀tẹ̀ tí ẹ̀ ń hù?

Gbogbo orí yín jẹ́ kìkìdá egbò,

gbogbo ọkàn yín sì rẹ̀wẹ̀sì.

6 Láti àtẹ́lẹsẹ̀ dé orí yín,

kò síbìkan tí ó gbádùn.

Gbogbo ara yín kún fún ọgbẹ́ ati egbò tí ń ṣẹ̀jẹ̀.

Ẹnikẹ́ni kò wẹ egbò yín, wọn kò dì wọ́n,

bẹ́ẹ̀ ni wọn kò fi òògùn sí wọn.

7 Orílẹ̀-èdè yín ti di ahoro,

wọ́n ti dáná sun àwọn ìlú yín.

Àwọn àjèjì sì ti jẹ ilẹ̀ yín run níṣojú yín.

Ó di ahoro bí èyí tí àwọn àjèjì wó palẹ̀.

8 Ó wá ku Jerusalẹmu bí àtíbàbà ninu ọgbà àjàrà,

ati bí ahéré ninu oko ẹ̀gúsí;

ó wá dàbí ìlú tí ogun dótì.

9 Bí kò bá ṣe pé OLUWA àwọn ọmọ ogun dá díẹ̀ sí ninu wa ni,

à bá rí bí i Sodomu,

à bá sì dàbí Gomora.

10 Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ OLUWA,

ẹ̀yin ìjòyè Sodomu:

Ẹ fetí sí ẹ̀kọ́ Ọlọrun wa,

ẹ̀yin ará Gomora

11 OLUWA ní,

“Kí ni gbogbo ẹbọ yín jámọ́ fún mi?

Àgbò tí ẹ fi ń rú ẹbọ sísun sí mi ti tó gẹ́ẹ́;

bẹ́ẹ̀ náà sì ni ọ̀rá ẹran àbọ́pa.

N kò ní inú dídùn sí ẹ̀jẹ̀ mààlúù tabi ti ọ̀dọ́ aguntan tabi ti òbúkọ.

12 Nígbà tí ẹ bá wá jọ́sìn níwájú mi,

ta ló bẹ̀ yín ní gbogbo gìrìgìrì lásán, tí ẹ̀ ń dà ninu àgbàlá mi.

13 Ẹ má mú ẹbọ asán wá fún mi mọ́;

ohun ìríra ni turari jẹ́ fún mi.

Àjọ̀dún ìbẹ̀rẹ̀ oṣù titun, ọjọ́ ìsinmi, ati pípe àpéjọ.

Ara mi kò gba ẹ̀ṣẹ̀ tí ẹ̀ ń dàpọ̀ mọ́ ẹ̀sìn mọ́.

14 Ninu ọkàn mi, mo kórìíra àwọn àjọ̀dún oṣù tuntun yín, ati àwọn àjọ̀dún pataki yín.

Wọ́n ti di ẹrù wúwo fún mi,

n kò lè gbé e mọ́, ó sú mi.

15 “Bí ẹ bá tẹ́wọ́ adura,

n óo gbé ojú mi kúrò lọ́dọ̀ yín.

Ẹ̀ báà tilẹ̀ gbadura, gbadura

n kò ní gbọ́;

nítorí ọwọ́ yín kún fún ẹ̀jẹ̀,

16 Ẹ wẹ̀, kí ara yín dá ṣáká.

Ẹ má hùwà burúkú níwájú mi mọ́.

Ẹ má ṣe iṣẹ́ ibi mọ́.

17 Ẹ lọ kọ́ bí eniyan tí ń ṣe rere.

Ẹ máa ṣe ẹ̀tọ́.

Ẹ máa ran ẹni tí ara ń ni lọ́wọ́.

Ẹ máa gbìjà aláìníbaba, kí ẹ sì máa gba ẹjọ́ opó rò.”

18 OLUWA ní, “Ẹ wá ná, ẹ jẹ́ kí á jọ sọ àsọyé pọ̀.

Bí ẹ̀ṣẹ̀ yín tilẹ̀ pọ́n bí iná,

yóo di funfun bí ẹfun.

Bí ó tilẹ̀ pupa bí aṣọ àlàárì,

yóo di funfun bí irun ọmọ aguntan funfun.

19 Bí ẹ bá fẹ́, tí ẹ sì gbọ́ràn,

ẹ óo jẹ ire ilẹ̀ náà.

20 Ṣugbọn tí ẹ bá kọ̀, tí ẹ sì ṣoríkunkun;

idà ni yóo run yín.”

Bẹ́ẹ̀ ni OLUWA sọ.

Ìlú tí Ó kún fún Ẹ̀ṣẹ̀

21 Ìlú tí ó ti jẹ́ olódodo rí tí ń ṣe bí aṣẹ́wó,

ìlú tí ó ti kún fún ẹ̀tọ́ ati òdodo rí, ti kún fún ìpànìyàn.

22 Fadaka rẹ ti di ìdàrọ́ mọ́ ọ lọ́wọ́.

Wọ́n ti fi omi lú ọtí waini rẹ.

23 Ọlọ̀tẹ̀ ni àwọn ìjòyè rẹ, ati ẹgbẹ́ olè;

gbogbo wọn ni wọ́n fẹ́ràn àbẹ̀tẹ́lẹ̀,

tí wọn sì ń wá ẹ̀bùn káàkiri.

Wọn kì í gbèjà aláìníbaba,

bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í gba ẹjọ́ opó rò.

24 Nítorí náà, OLUWA àwọn ọmọ ogun, Alágbára Israẹli ní:

“N óo bínú sí àwọn ọ̀tá mi,

n óo sì gbẹ̀san lára àwọn tí ó kórìíra mi.

25 Nígbà tí mo bá gbá ọ mú,

n óo finá jó gbogbo àìdára rẹ dànù.

N óo sì mú gbogbo ìbàjẹ́ rẹ kúrò.

26 N óo dá àwọn onídàájọ́ rẹ pada sí ipò tí wọn ti wà tẹ́lẹ̀.

Ati àwọn olùdámọ̀ràn rẹ,

lẹ́yìn náà a óo máa pè ọ́ ní ìlú olódodo.”

27 A óo fi ẹ̀tọ́ ra Sioni pada;

a óo sì fi òdodo ra àwọn tí ó bá ronupiwada ninu rẹ pada.

28 Ṣugbọn a óo pa àwọn ọlọ̀tẹ̀ ati àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ run,

àwọn tí ó kọ OLUWA sílẹ̀ yóo sì ṣègbé.

29 Ojú yóo tì yín, fún àwọn igi Oaku tí ẹ nífẹ̀ẹ́ láti máa bọ.

Ojú yóo sì tì yín fún àwọn ọgbà oriṣa tí ẹ yàn.

30 Nítorí pé ẹ óo dàbí igi oaku tí ó wọ́wé,

ati bí ọgbà tí kò lómi.

31 Alágbára yóo dàbí ògùṣọ̀,

iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ bí ìṣáná.

Àwọn mejeeji ni yóo jóná pọ̀,

kò sì ní sí ẹni tí yóo lè pa iná náà.

Categories
AISAYA

AISAYA 2

Alaafia Ayérayé

1 Ọ̀rọ̀ tí Aisaya ọmọ Amosi sọ nípa Juda ati Jerusalẹmu nìyí:

2 Ní ọjọ́ iwájú

òkè ilé OLUWA yóo fi ìdí múlẹ̀, gẹ́gẹ́ bí òkè tí ó ga jùlọ,

a óo sì gbé e ga ju àwọn òkè yòókù lọ.

Gbogbo orílẹ̀-èdè yóo wá sibẹ.

3 Ọpọlọpọ eniyan ni yóo wá, tí wọn yóo máa wí pé:

“Ẹ wá! Ẹ jẹ́ kí á gun òkè OLUWA lọ,

kí á lọ sí ilé Ọlọrun Jakọbu,

kí ó lè kọ́ wa ní ìlànà rẹ̀,

kí á sì lè rìn ní ọ̀nà rẹ̀.

Nítorí pé láti Sioni ni òfin Ọlọrun yóo ti jáde wá

ọ̀rọ̀ OLUWA yóo sì wá láti Jerusalẹmu.”

4 Yóo ṣe ìdájọ́ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè;

yóo sì bá ọpọlọpọ eniyan wí.

Wọn yóo fi idà wọn rọ ọkọ́,

wọn yóo sì fi ọ̀kọ̀ wọn rọ dòjé.

Àwọn orílẹ̀-èdè kò ní yọ idà sí ara wọn mọ́,

wọn kò sì ní kọ́ ogun jíjà mọ́.

5 Ẹ̀yin ìdílé Jakọbu

ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á rìn ninu ìmọ́lẹ̀ OLUWA.

A óo pa Ìgbéraga Run.

6 Nítorí o ti ta àwọn eniyan rẹ nù,

àní, ìdílé Jakọbu.

Nítorí pé àwọn aláfọ̀ṣẹ ará ìhà ìlà oòrùn pọ̀ láàrin wọn,

àwọn alásọtẹ́lẹ̀ sì pọ̀ bíi ti àwọn ará Filistini,

Wọ́n ti gba àṣà àwọn àjèjì.

7 Wúrà ati fadaka kún ilẹ̀ wọn,

ìṣúra wọn kò sì lópin.

Ẹṣin kún ilẹ̀ wọn,

kẹ̀kẹ́ ogun wọn kò sì lóǹkà.

8 Ilẹ̀ wọn kún fún oriṣa,

wọ́n ń bọ iṣẹ́ ọwọ́ ara wọn,

wọ́n ń wólẹ̀ fún ohun tí wọ́n fọwọ́ ara wọn ṣe.

9 Bẹ́ẹ̀ ni eniyan ṣe tẹ ara rẹ̀ lórí ba

tí ó sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀.

Oluwa, máṣe dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n.

10 Ẹ wọnú àpáta lọ,

kí ẹ sì farapamọ́ sinu ilẹ̀.

Ẹ sá fún ibinu OLUWA

ati ògo ọlá ńlá rẹ̀.

11 A óo rẹ ọlọ́kàn gíga eniyan sílẹ̀,

a óo sì rẹ àwọn onigbeeraga sílẹ̀;

OLUWA nìkan ni a óo gbéga ní ọjọ́ náà.

12 Nítorí OLUWA àwọn ọmọ ogun ti ya ọjọ́ kan sọ́tọ̀,

tí yóo dojú ìjà kọ àwọn agbéraga,

ati àwọn ọlọ́kàn gíga,

ati gbogbo nǹkan tí à ń gbéga.

13 Yóo dojú kọ gbogbo igi Kedari ti Lẹbanoni,

tí ó ga fíofío, ati gbogbo igi oaku ilẹ̀ Baṣani;

14 ati gbogbo àwọn òkè ńláńlá,

ati gbogbo òkè gíga,

15 ati gbogbo ilé-ìṣọ́ gíga

ati gbogbo odi tí ó lágbára,

16 ati gbogbo ọkọ̀ ojú omi láti ìlú Taṣiṣi,

ati gbogbo ọkọ̀ tí ó dára.

17 Àwọn ọlọ́kàn gíga yóo di ẹni ilẹ̀,

a óo sì rẹ àwọn onigbeeraga sílẹ̀.

OLUWA nìkan ni a óo gbéga ní ọjọ́ náà,

18 àwọn oriṣa yóo sì pòórá patapata.

19 Àwọn eniyan yóo sá sinu ihò àpáta,

wọn yóo sì wọ inú ihò ilẹ̀ lọ,

nígbà tí wọ́n bá ń sá fún ibinu OLUWA,

ati ògo ọlá ńlá rẹ̀

nígbà tí ó bá dìde láti mi ayé tìtì.

20 Ní ọjọ́ náà,

àwọn eniyan óo kó àwọn ère fadaka wọn dànù,

ati àwọn ère wúrà tí wọ́n fi ọwọ́ ara wọn ṣe, tí wọn tún ń bọ.

Wọn yóo dà wọ́n fún àwọn èkúté ati àwọn àdán.

21 Wọn óo wọ inú pàlàpálá àpáta,

ati inú ihò àwọn òkè gíga;

nígbà tí wọn bá ń sá fún ibinu OLUWA,

ati ògo ọlá ńlá rẹ̀,

nígbà tí ó bá dìde láti mi ayé tìtì.

22 Ẹ má gbẹ́kẹ̀lé eniyan mọ́.

Ẹlẹ́mìí ni òun alára,

nítorí pé kí ni ó lè ṣe?

Categories
AISAYA

AISAYA 3

Ìdàrúdàpọ̀ Ní Jerusalẹmu

1 Wò ó! OLUWA, OLUWA àwọn ọmọ ogun yóo mú

gbogbo àwọn tí àwọn eniyan gbójúlé kúrò,

ati àwọn nǹkan tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé ní Jerusalẹmu ati Juda.

Yóo gba gbogbo oúnjẹ tí wọ́n gbójúlé,

ati gbogbo omi tí wọ́n fi ẹ̀mí tẹ̀.

2 Yóo mú àwọn alágbára ati àwọn ọmọ ogun kúrò,

pẹlu àwọn onídàájọ́ ati àwọn wolii,

àwọn aláfọ̀ṣẹ ati àwọn àgbààgbà;

3 àwọn olórí aadọta ọmọ ogun, ati àwọn ọlọ́lá,

àwọn adáhunṣe ati àwọn pidánpidán, ati àwọn olóògùn.

4 Ọdọmọkunrin ni OLUWA yóo fi jẹ olórí wọn,

àwọn ọmọde ni yóo sì máa darí wọn.

5 Àwọn eniyan náà yóo máa fìyà jẹ ara wọn,

olukuluku yóo máa fìyà jẹ ẹnìkejì rẹ̀,

àwọn aládùúgbò yóo sì máa fìyà jẹ ara wọn.

Ọmọde yóo nàró mọ́ àgbàlagbà,

àwọn mẹ̀kúnnù yóo máa dìde sí àwọn ọlọ́lá.

6 Nígbà tí ẹnìkan bá dì mọ́ arakunrin rẹ̀,

ninu ilẹ̀ baba rẹ̀, tí ó sọ fún un pé,

“Ìwọ ní aṣọ ìlékè,

nítorí náà, jẹ́ olórí fún wa;

gbogbo ahoro yìí yóo sì wà lábẹ́ àkóso rẹ.”

7 Ní ọjọ́ náà, ẹni tí wọn sọ pé kí ó jẹ olórí yóo kígbe pé,

“Èmi kò ní jẹ oyè alátùn-únṣe.

N kò ní oúnjẹ nílé

bẹ́ẹ̀ ni kò sí aṣọ.

Ẹ má fi mí ṣe olórí yín.”

8 Nítorí Jerusalẹmu ti kọsẹ̀,

Juda sì ti ṣubú.

Nítorí ọ̀rọ̀ ẹnu wọn ati ìṣe wọn lòdì sí OLUWA,

wọ́n ń tàpá sí ògo wíwà rẹ̀.

9 Ìwà àgàbàgebè wọn ń takò wọ́n;

wọ́n ń polongo ẹ̀ṣẹ̀ wọn bíi ti Sodomu:

Wọn kò fi bò rárá.

Ègbé ni fún wọn,

nítorí pé àwọn ni wọ́n mú ibi wá sórí ara wọn.

10 Sọ fún àwọn olódodo pé yóo dára fún wọn

nítorí wọn yóo jèrè iṣẹ́ wọn.

11 Ègbé ni fún àwọn eniyan burúkú,

kò ní dára fún wọn.

Nítorí wọn óo jèrè iṣẹ́ ọwọ́ wọn.

12 Ẹ wá wo àwọn eniyan mi!

Ọmọde ni àwọn olórí àwọn eniyan mi;

àwọn obinrin ní ń pàṣẹ lé wọn lórí.

Ẹ̀yin eniyan mi,

àwọn olórí yín ń ṣì yín lọ́nà,

wọ́n sì ti da ọ̀nà yín rú.

OLUWA Dá Àwọn Eniyan Rẹ̀ Lẹ́jọ́

13 OLUWA ti dìde láti ro ẹjọ́ tirẹ̀;

ó ti múra tán láti dá àwọn eniyan rẹ̀ lẹ́jọ́

14 OLUWA yóo pe àwọn àgbààgbà ati àwọn olórí àwọn eniyan rẹ̀

siwaju ìtẹ́ ìdájọ́,

yóo sọ fún wọn pé;

“Ẹ̀yin ni ẹ jẹ ọgbà àjàrà mi run,

ohun tí ẹ jí nílé àwọn talaka ń bẹ nílé yín.

15 Kí ni ẹ rò tí ẹ fi ń tẹ àwọn eniyan mi ní àtẹ̀rẹ́,

tí ẹ̀ ń fi ojú àwọn talaka gbolẹ̀?”

Ìkìlọ̀ fún Àwọn Obinrin Jerusalẹmu

16 OLUWA ní,

“Nítorí pé àwọn obinrin Jerusalẹmu jẹ́ onigbeeraga,

bí wọn bá ń rìn, wọn á gbé ọrùn sókè gangan;

wọn á máa ṣẹ́jú bí wọn tí ń yan lọ.

Ṣaworo tí ó wà lọ́rùn ẹsẹ̀ wọn a sì máa dún

bí wọ́n tí ń gbésẹ̀ lọ́kọ̀ọ̀kan.

17 OLUWA yóo mú kí orí àwọn obinrin Jerusalẹmu pá;

yóo ṣí aṣọ lórí wọn.”

18 Ní ọjọ́ náà, OLUWA yóo já gbogbo nǹkan ọ̀ṣọ́ wọn dànù; ati ṣaworo ẹsẹ̀ wọn ni, ati ẹ̀gbà orí wọn; ẹ̀gbà ọrùn wọn;

19 ati yẹtí wọn, ẹ̀gbà ọwọ́ wọn ati ìbòrí wọn.

20 Gèlè wọn ati ìlẹ̀kẹ̀ ẹsẹ̀ wọn, ati ìborùn, ìgò ìpara wọn ati òògùn,

21 òrùka ọwọ́ wọn ati òrùka imú,

22 ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ ati ẹ̀wù àwọ̀lékè ati aṣọ wọn, ati àpò

23 ati àwọn aṣọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ funfun, àwọn ìborùn olówó ńlá.

24 Òórùn burúkú yóo wà dípò òórùn dídùn ìpara,

okùn yóo wà dípò ọ̀já;

orí pípá yóo dípò irun tí wọ́n ṣe lọ́ṣọ̀ọ́,

aṣọ ọ̀fọ̀ yóo dípò aṣọ olówó iyebíye.

Ìtìjú yóo bò yín dípò ẹwà.

25 Idà ni yóo pa àwọn ọkunrin yín,

àwọn akikanju yín yóo kú sógun.

26 Ọ̀fọ̀ ati ẹkún yóo pọ̀ ní ẹnu ibodè Jerusalẹmu.

Yóo dàbí obinrin tí wọ́n tú sí ìhòòhò,

tí ó jókòó ní ilẹ̀ẹ́lẹ̀.

Categories
AISAYA

AISAYA 4

1 Tí ó bá di ìgbà náà, obinrin meje yóo rọ̀ mọ́ ọkunrin kan ṣoṣo, wọn óo máa bẹ̀ ẹ́ pé, “A óo máa bọ́ ara wa, a óo sì máa dá aṣọ sí ara wa lọ́rùn. Ṣá máa jẹ́ ọkọ wa, kí á máa jẹ́ orúkọ rẹ; kí o mú ìtìjú kúrò lọ́rọ̀ wa.”

A óo Tún Jerusalẹmu Kọ́

2 Tí ó bá di ìgbà náà, ẹ̀ka igi OLUWA yóo di ohun ẹwà ati iyì. Èso ilẹ̀ náà yóo sì di ohun ògo ati àmúyangàn fún àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n bá kù.

3 Eniyan mímọ́ ni a óo máa pe àwọn tí wọ́n bá kù ní Sioni, àní, àwọn tí wọ́n ṣẹ́kù ní Jerusalẹmu; gbogbo àwọn tí a bá kọ orúkọ wọn sílẹ̀ pé wọ́n wà láàyè ní Jerusalẹmu.

4 Nígbà tí OLUWA bá ti fọ èérí Jerusalẹmu dànù, tí ó sì jó o níná tí ó sì mú ẹ̀bi ìpànìyàn kúrò níbẹ̀, nípa pé kí wọn máa ṣe ìdájọ́ òtítọ́,

5 ní ọ̀sán, yóo mú kí ìkùukùu bo gbogbo òkè Sioni ati àwọn tí ó ń péjọ níbẹ̀; ní alẹ́, yóo sì fi èéfín ati ìtànṣán ìmọ́lẹ̀ bò wọ́n. Ògo OLUWA yóo bò wọ́n bí àtíbàbà ati ìbòrí.

6 Yóo dáàbò bò wọ́n lọ́wọ́ oòrùn lọ́sàn-án, yóo jẹ́ ibi ìsásí ati ààbò fún wọn lọ́wọ́ ìjì ati òjò.

Categories
AISAYA

AISAYA 5

Orin Ọgbà Àjàrà

1 Ẹ jẹ́ kí n kọrin kan fún olùfẹ́ mi,

kí n kọrin nípa ọgbà àjàrà rẹ̀.

Olùfẹ́ mi ní ọgbà àjàrà kan

ní orí òkè kan tí ilẹ̀ ibẹ̀ lọ́ràá.

2 Ó kọ́ ilẹ̀ rẹ̀, ó sì ṣa gbogbo òkúta ibẹ̀ kúrò.

Ó gbin àjàrà dáradára sinu rẹ̀.

Ó kọ́ ilé ìṣọ́ gíga sí ààrin rẹ̀,

ó sì ṣe ibi tí wọn yóo ti máa fún ọtí sibẹ.

Ó ń retí kí àjàrà rẹ̀ so,

ṣugbọn èso kíkan ni ó so.

3 Ẹ̀yin ará Jerusalẹmu, ati ẹ̀yin ará Juda,

mo bẹ̀ yín, ẹ wá ṣe ìdájọ́ láàrin èmi ati ọgbà àjàrà mi.

4 Kí ló tún kù tí ó yẹ kí n ṣe sí ọgbà àjàrà mi tí n kò ṣe?

Ìgbà tí mo retí kí ó so èso dídùn,

kí ló dé tí ó fi so èso kíkan?

5 Nisinsinyii n óo sọ ohun tí n óo ṣe sí ọgbà àjàrà mi fun yín.

N óo tú ọgbà tí mo ṣe yí i ká,

iná yóo sì jó o.

N óo wó odi tí mo mọ yí i ká,

wọn yóo sì tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀.

6 N óo jẹ́ kí ó di igbó,

ẹnikẹ́ni kò ní ro ó mọ́,

wọn kò sì ní tọ́jú rẹ̀ mọ́.

Ẹ̀gún ati ẹ̀wọ̀n agogo ni yóo hù níbẹ̀.

N óo pàṣẹ fún òjò

kí ó má rọ̀ sórí rẹ̀ mọ́.

7 Nítorí ilé Israẹli ni ọgbà àjàrà OLUWA ọmọ ogun,

àwọn ará Juda ni àjàrà dáradára tí ó gbìn sinu rẹ̀.

Ó ń retí kí wọn máa ṣe ẹ̀tọ́,

ṣugbọn kàkà bẹ́ẹ̀ wọ́n ń paniyan;

ó ń retí ìwà òdodo,

ṣugbọn kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn tí wọn ń ni lára ni wọ́n ń kígbe.

Ìwà Burúkú Eniyan

8 Ègbé ni fún àwọn tí ó ń kọ́lé mọ́lé,

tí wọn ń gba ilẹ̀ kún ilẹ̀,

títí tí kò fi sí ilẹ̀ mọ́,

kí ẹ̀yin nìkan baà lè máa gbé ilẹ̀ náà.

9 OLUWA ọmọ ogun ti búra lójú mi, ó ní,

“Láìsí àní-àní, ọpọlọpọ ilé ni yóo di ahoro,

ọ̀pọ̀ ilé ńláńlá, ati ilé dáradára yóo sì wà láìsí olùgbé.

10 Apẹ̀rẹ̀ èso àjàrà kan ni a óo rí ká ninu ọgbà àjàrà sarè mẹ́wàá.

Kóńgò èso kan ni ẹni tí ó gbin kóńgò marun-un yóo rí ká.”

11 Ègbé ni fún àwọn tí wọ́n jí ní òwúrọ̀ kutukutu,

láti máa wá ọtí líle kiri,

tí wọ́n ń mu ún títí di ìrọ̀lẹ́,

títí tí ọtí yóo fi máa pa wọ́n!

12 Dùùrù, hapu, ìlù, fèrè ati ọtí waini wà níbi àsè wọn;

ṣugbọn wọn kì í bìkítà fún iṣẹ́ Ọlọrun,

wọn kìí sìí náání iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.

13 Nítorí náà àwọn eniyan mi óo lọ sí oko ẹrú nítorí àìmòye wọn,

ebi ni yóo pa àwọn ọlọ́lá wọn ní àpakú,

òùngbẹ óo sì gbẹ ọpọlọpọ wọn.

14 Isà òkú ti ṣetán, yóo gbé wọn mì,

ó ti yanu kalẹ̀.

Àwọn ọlọ́lá Jerusalẹmu yóo já sinu rẹ́,

ati ọ̀pọ̀ ninu àwọn ará ìlú,

ati àwọn tí ń fi ìlú Jerusalẹmu yangàn.

15 A tẹ eniyan lórí ba,

a sì rẹ̀ wọ́n sílẹ̀

ojú àwọn onigbeeraga yóo sì wálẹ̀.

16 Ṣugbọn OLUWA àwọn ọmọ ogun

ni a óo gbéga ninu ẹ̀tọ́ nítorí ìdájọ́ òdodo

Ọlọrun Mímọ́ yóo fi ara rẹ̀ hàn, pé mímọ́ ni òun ninu òdodo.

17 Nígbà náà ni àwọn ọ̀dọ́ aguntan yóo máa jẹ oko ninu pápá oko wọn

àwọn àgbò ati ewúrẹ́ yóo sì máa jẹko ninu ahoro wọn.

18 Àwọn tí ń ṣe àfọwọ́fà ẹ̀ṣẹ̀ gbé!

Àwọn tí wọn ń fi ìwà aiṣododo fa ẹ̀ṣẹ̀ bí ẹni tí ń fi okùn fa ẹṣin.

19 Tí wọn ń wí pé:

“Kí ó tilẹ̀ ṣe kíá,

kí ó ṣe ohun tí yóo ṣe, kí á rí i.

Jẹ́ kí àbá Ẹni Mímọ́ Israẹli di òtítọ́

kí ó ṣẹlẹ̀, kí á lè mọ̀ ọ́n!”

20 Àwọn tí ń pe ibi ní ire gbé;

tí wọn ń pe ire ní ibi!

Àwọn tí wọn ń fi òkùnkùn ṣe ìmọ́lẹ̀,

tí wọn sì fi ìmọ́lẹ̀ ṣe òkùnkùn!

Tí wọ́n fi ìkorò ṣe adùn,

tí wọ́n sì fi adùn ṣe ìkorò.

21 Àwọn tí ó gbọ́n lójú ara wọn gbé;

tí wọ́n ka ara wọn kún ẹni tí ó ní ìmọ̀!

22 Àwọn tí wọ́n jẹ́ ọ̀gá ninu ọtí mímu gbé;

tí wọ́n jẹ́ akikanju

bí ó bá di pé kí á da ọtí líle pọ̀ mọ́ ara wọn!

23 Àwọn tí wọn ń dá ẹni tí ó jẹ̀bi sílẹ̀

nígbà tí wọ́n bá ti gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ tán;

tí wọn kì í jẹ́ kí aláìṣẹ̀ rí ẹ̀tọ́ gbà.

24 Nítorí náà, bí iná tíí jó àgékù igi kanlẹ̀,

tíí sìí jó ewéko ní àjórun;

bẹ́ẹ̀ ní gbòǹgbò wọn yóo ṣe rà,

tí ìtànná wọn yóo sì fẹ́ lọ bí eruku.

Nítorí wọ́n kọ òfin OLUWA àwọn ọmọ ogun sílẹ̀,

wọ́n sì kẹ́gàn ọ̀rọ̀ Ẹni Mímọ́ Israẹli.

25 Nítorí náà ni inú ṣe bí OLUWA sí àwọn eniyan rẹ̀,

ó sì na ọwọ́ rẹ̀, ó sì pa wọ́n,

àwọn òkè sì mì tìtì.

Òkú wọn dàbí pàǹtí láàrin ìgboro,

sibẹsibẹ inú OLUWA kò rọ̀,

bẹ́ẹ̀ ni kò sì dá ọwọ́ ìjà dúró.

26 Ó ta àsíá, ó fi pe orílẹ̀-èdè kan tí ó wà ní òkèèrè;

ó sì fọn fèrè sí i láti òpin ayé.

Wò ó! Àwọn eniyan orílẹ̀-èdè náà ń bọ̀ kíákíá.

27 Kò rẹ ẹnikẹ́ni ninu wọn,

ẹnikẹ́ni ninu wọn kò fẹsẹ̀ kọ.

Ẹyọ ẹnìkan wọn kò sì sùn,

bẹ́ẹ̀ ni wọn kò tòògbé.

Àmùrè ẹnìkankan kò tú,

bẹ́ẹ̀ ni okùn bàtà ẹnìkankan kò já.

28 Ọfà wọn mú wọ́n kẹ́ ọrun wọn.

Pátákò ẹsẹ̀ ẹṣin wọn le bí òkúta akọ;

ẹsẹ̀ kẹ̀kẹ́ ogun wọn dàbí ìjì líle.

29 Bíbú wọn dàbí ti kinniun,

wọn a bú ramúramù bí ọmọ kinniun,

wọn a kígbe, wọn a sì ki ohun ọdẹ wọn mọ́lẹ̀,

wọn a gbé e lọ, láìsí ẹni tí ó lè gbà á lọ́wọ́ wọn.

30 Wọn óo hó lé Israẹli lórí lọ́jọ́ náà

bí ìgbà tí omi òkun ń hó.

Bí eniyan bá wọ ilẹ̀ náà yóo rí òkùnkùn ati ìnira.

Ìkùukùu rẹ̀ yóo sì bo ìmọ́lẹ̀.

Categories
AISAYA

AISAYA 6

Ọlọrun Pe Aisaya láti jẹ́ Wolii

1 Ní ọdún tí Usaya Ọba kú, mo rí OLUWA: ó jókòó lórí ìtẹ́, a gbé e ga sókè, aṣọ ìgúnwà rẹ̀ sì kún inú tẹmpili.

2 Àwọn Serafu dúró lókè rẹ̀. Ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu wọn ní ìyẹ́ mẹfa mẹfa: ó fi meji bo ojú, ó fi meji bo ẹsẹ̀, ó sì ń fi meji fò.

3 Ekinni ń ké sí ekeji pé:

“Mímọ́, mímọ́, mímọ́ ni OLUWA àwọn ọmọ ogun;

gbogbo ayé kún fún ògo rẹ̀.”

4 Ìpìlẹ̀ ilé náà mì títí nígbà tí ẹni náà kígbe, èéfín sì kún ilé náà.

5 Mo bá pariwo, mo ní, “Mo gbé! Mo ti sọnù, nítorí pé ọ̀rọ̀ ẹnu mi kò mọ́, ọ̀rọ̀ ẹnu àwọn tí mò ń gbé ààrin wọn náà kò sì mọ́. Bẹ́ẹ̀ sì ni mo ti fi ojú rí Ọba, OLUWA àwọn ọmọ ogun.”

6 Ọ̀kan ninu àwọn Serafu náà bá fi ẹ̀mú mú ẹ̀yinná kan lórí pẹpẹ, ó mú un lọ́wọ́, ó bá fò wá sọ́dọ̀ mi.

7 Ó sì fi ògúnná náà kàn mí lẹ́nu, ó ní: “Wò ó, èyí ti kàn ọ́ ní ètè: A ti mú ẹ̀bi rẹ kúrò, a sì ti dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́.”

8 Mo wá gbọ́ ohùn OLUWA ó ní, “Ta ni kí n rán? Ta ni yóo lọ fún wa?”

Mo bá dáhùn, mo ní: “Èmi nìyí, rán mi.”

9 OLUWA bá ní:

“Lọ, sọ fún àwọn eniyan wọnyi pé;

wọn óo gbọ́ títí, ṣugbọn kò ní yé wọn;

wọn óo wò títí, ṣugbọn wọn kò ní rí nǹkankan.

10 Mú kí ọkàn àwọn eniyan wọnyi ó yigbì,

jẹ́ kí etí wọn di.

Fi nǹkan bò wọ́n lójú,

kí wọn má baà ríran,

kí wọn má sì gbọ́ràn,

kí òye má baà yé wọn,

kí wọn má baà yipada,

kí wọn sì rí ìwòsàn.”

11 Mo bá bi í pé: “OLUWA mi, títí di ìgbà wo?”

Ó sì dáhùn pé: “Títí tí àwọn ìlú yóo fi di ahoro, láìsí ẹni tí yóo máa gbé inú wọn; títí tí ilé yóo fi tú láì ku ẹnìkan, títí tí ilẹ̀ náà yóo fi di ahoro patapata.

12 Tí OLUWA yóo kó àwọn eniyan lọ sí ilẹ̀ òkèèrè, tí ibi tí a kọ̀tì yóo sì di pupọ ní ilẹ̀ náà.

13 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìdámẹ́wàá àwọn eniyan náà ni ó kù ní ilẹ̀ náà, sibẹsibẹ iná yóo tún jó o bí igi terebinti tabi igi Oaku, tí kùkùté rẹ̀ wà lórí ilẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n gé e lulẹ̀.”

Èso mímọ́ ni kùkùté rẹ̀.

Categories
AISAYA

AISAYA 7

Aisaya Jíṣẹ́ OLUWA fún Ahasi Ọba

1 Nígbà ayé Ahasi, ọmọ Jotamu, ọmọ Usaya, ọba Juda, Resini Ọba Siria ati Peka ọmọ Remalaya, ọba Israẹli wá gbé ogun ti Jerusalẹmu, ṣugbọn wọn kò lè ṣẹgun rẹ̀.

2 Nígbà tí ìròyìn dé ilé ọba Dafidi pé àwọn ará Siria ati Efuraimu ń gbógun bọ̀, ọkàn òun ati àwọn eniyan rẹ̀ mì tìtì bí afẹ́fẹ́ tíí mi igi ninu igbó.

3 OLUWA sọ fún Aisaya pé, “Lọ bá Ahasi, ìwọ ati Ṣeari Jaṣubu, ọmọ rẹ, ní òpin ibi tí wọ́n fa omi dé ní ọ̀nà àwọn alágbàfọ̀.

4 Kí o sọ fún un pé, ṣọ́ra, farabalẹ̀, má sì bẹ̀rù. Má ṣe jẹ́ kí àyà rẹ já rárá nítorí ibinu gbígbóná Resini ati Siria, ati ti ọmọ Remalaya, nítorí wọn kò yàtọ̀ sí àjókù igi iná meji tí ń rú èéfín.

5 Nítorí pé Siria, pẹlu Efuraimu ati ọmọ Remalaya ti pète ati ṣe ọ́ ní ibi. Wọ́n ń sọ pé,

6 ‘Ẹ jẹ́ kí á lọ gbógun ti Juda, kí á dẹ́rùbà á, ẹ jẹ́ kí á ṣẹgun rẹ̀ kí á sì gbà á, kí á fi ọmọ Tabeeli jọba lórí rẹ̀!’

7 “Àbá tí wọn ń dá kò ní ṣẹ, ète tí wọn ń pa kò ní rí bẹ́ẹ̀.

8 Ṣebí Damasku ni olú-ìlú Siria, Resini sì ni olórí Damasku. Láàrin ìsinyìí sí ọdún marundinlaadọrin, Efuraimu yóo fọ́nká, kò sì ní jẹ́ orílẹ̀-èdè mọ́.

9 Ṣebí Samaria ni olú-ìlú Efuraimu, Ọmọ Remalaya sì ni olórí Samaria. Bí ẹ kò bá gbàgbọ́ ẹ kò ní fẹsẹ̀ múlẹ̀.”

Àmì Imanuẹli

10 OLUWA tún sọ fún Ahasi pé:

11 “Bèèrè àmì tí ó bá wù ọ́ lọ́wọ́ OLUWA Ọlọrun rẹ–ìbáà jìn bí isà òkú, tabi kí ó ga bí ojú ọ̀run.”

12 Ṣugbọn Ahasi dáhùn, ó ní: “Èmi kò ní bèèrè nǹkankan, n kò ní dán OLUWA wò.”

13 Aisaya bá dáhùn pé, “Ẹ gbọ́, ẹ̀yin ọmọ Dafidi, ṣé eniyan tí ẹ̀ ń yọ lẹ́nu kò to yín, Ọlọrun mi alára lókù tí ẹ tún ń yọ lẹ́nu?

14 Nítorí náà, OLUWA fúnrarẹ̀ yóo fun yín ní àmì kan. Ẹ gbọ́! Ọlọ́mọge kan yóo lóyún yóo sì bí ọmọkunrin kan, yóo pe orúkọ rẹ̀ ní Imanuẹli.

15 Nígbà tí yóo bá fi mọ bí a ti í kọ nǹkan burúkú, tí a sì í yan nǹkan rere, wàrà ati oyin ni àwọn eniyan yóo máa jẹ.

16 Nítorí pé kí ọmọ náà tó mọ bí a ti í kọ nǹkan burúkú tí a sì í yan nǹkan rere, ilẹ̀ àwọn ọba mejeeji tí wọn ń bà ọ́ lẹ́rù yìí yóo ti di ìkọ̀sílẹ̀.

17 “OLUWA yóo mú ọjọ́ burúkú dé bá ìwọ ati àwọn eniyan rẹ ati ilé baba rẹ, ọjọ́ tí kò ì tíì sí irú rẹ̀ rí, láti ìgbà tí Efuraimu ti ya kúrò lára Juda, OLUWA ń mú ọba Asiria bọ̀.

18 “Ní ọjọ́ náà OLUWA yóo súfèé pe àwọn eṣinṣin tí ó wà ní orísun gbogbo odò Ijipti ati àwọn oyin tí ó wà ní ilẹ̀ Asiria.

19 Gbogbo wọn yóo sì rọ́ wá sí ààrin àwọn àfonífojì, ati gbogbo kọ̀rọ̀ kọ̀rọ̀ ní ààrin àpáta, ati ara gbogbo igi ẹlẹ́gùn-ún ati gbogbo pápá.

20 “Ní ọjọ́ náà, OLUWA yóo mú ọba Asiria wá láti òdìkejì odò. Yóo lò ó bí abẹ ìfárí, yóo fi fá irun orí ati irun ẹsẹ̀ dànù, ati gbogbo irùngbọ̀n pàápàá.

21 “Ní ọjọ́ náà, eniyan yóo máa sin ẹyọ mààlúù kékeré kan ati aguntan meji péré,

22 wàrà tí yóo máa rí fún yóo pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé wàrà ati oyin ni yóo máa fi ṣe oúnjẹ jẹ. Nítorí pé wàrà ati oyin ni àwọn tí ó kù ní ilẹ̀ náà yóo máa jẹ.

23 “Ní ọjọ́ náà, gbogbo ibi tí ẹgbẹrun ìtàkùn àjàrà wà, tí owó rẹ̀ tó ẹgbẹrun ṣekeli fadaka, yóo di igbó ẹ̀gún ẹ̀wọ̀n agogo ati ẹ̀gún ọ̀gàn.

24 Àwọn eniyan yóo kó ọrun ati ọfà wá sibẹ, nítorí gbogbo ilẹ̀ náà yóo di igbó ẹ̀gún ẹ̀wọ̀n agogo ati ẹ̀gún ọ̀gàn.

25 Gbogbo ara òkè tí wọn tí ń fi ọkọ́ ro tẹ́lẹ̀, ẹnikẹ́ni kò ní lè débẹ̀ mọ́, nítorí ìbẹ̀rù ẹ̀wọ̀n agogo ati ẹ̀gún ọ̀gàn, gbogbo ibẹ̀ yóo wá di ibi tí mààlúù ati aguntan yóo ti máa jẹko.”

Categories
AISAYA

AISAYA 8

Ọmọ Aisaya jẹ́ Àmì fún Àwọn Eniyan

1 Lẹ́yìn náà, OLUWA sọ fún mi pé, “Mú ìwé kan tí ó fẹ̀, kí o kọ Maheriṣalali-haṣi-basi sí i lórí gàdàgbà gàdàgbà.”

2 Mo bá pe Alufaa Uraya ati Sakaraya, ọmọ Jebẹrẹkaya, kí wọn wá ṣe ẹlẹ́rìí mi nítorí wọ́n jẹ́ olóòótọ́.

3 Nígbà tí mo bá iyawo mi, tí òun náà jẹ́ wolii lò pọ̀, ó lóyún, ó sì bí ọmọkunrin. OLUWA bá sọ fún mi pé kí n sọ ọmọ náà ní Maheriṣalali-haṣi-basi.

4 Nítorí kí ọmọ náà tó mọ bí a tí ń pe ‘Baba mi’ tabi ‘Mama mi’, wọn óo ti kó àwọn nǹkan alumọni Damasku ati ìkógun Samaria lọ sí Asiria.

Ọba Asiria ń Bọ̀ Wá

5 OLUWA tún bá mi sọ̀rọ̀ ó ní,

6 “Nítorí pé àwọn eniyan wọnyi kọ omi Ṣiloa tí ń ṣàn wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́ sílẹ̀, wọ́n wá ń gbọ̀n jìnnìjìnnì níwájú Resini ati ọmọ Remalaya,

7 nítorí náà, ẹ wò ó, OLUWA yóo gbé ọba Asiria ati gbogbo ògo rẹ̀ dìde wá bá wọn, yóo sì bò wọ́n mọ́lẹ̀ bí omi odò Yufurate, tí ó kún àkúnya, tí ó sì kọjá bèbè rẹ̀.

8 Yóo ya wọ Juda, yóo sì bò ó mọ́lẹ̀ bí ó ti ń ṣàn kọjá lọ, títí yóo fi mù ún dé ọrùn. Yóo ya wọ inú ilẹ̀ rẹ̀ látòkè délẹ̀; yóo sì bo gbogbo rẹ̀ mọ́lẹ̀. Kí Ọlọrun wà pẹlu wa.”

9 Ẹ̀yin orílẹ̀-èdè, ẹ kó ara yín jọ!

A óo fọ yín túútúú.

Ẹ fetí sílẹ̀, gbogbo ẹ̀yin ará ilẹ̀ òkèèrè.

Ẹ di ara yín ní àmùrè;

a óo fọ yín túútúú.

Ẹ di ara yín ní àmùrè,

a óo fọ yín túútúú.

10 Bí ẹ gbìmọ̀ pọ̀ ìmọ̀ yín yóo di òfo.

Ohun yòówù tí ẹ lè sọ, àpérò yín yóo di asán.

Nítorí pé Ọlọrun wà pẹlu wa.

OLUWA Kìlọ̀ fún Wolii

11 Nítorí ọwọ́ agbára ni OLUWA fi lé mi lára, nígbà tí ó ń sọ èyí fún mi. Ó sì ti kìlọ̀ fún mi pé kí n má bá àwọn eniyan wọnyi rìn, ó ní,

12 “Ìwọ kò gbọdọ̀ lọ́wọ́ sí ọ̀tẹ̀ tí àwọn eniyan yìí ń dì. Bẹ́ẹ̀ ni o kò gbọdọ̀ bẹ̀rù ohun tí wọn ń bẹ̀rù.

13 OLUWA àwọn ọmọ ogun nìkan ni kí o kà sí mímọ́, òun ni kí ẹ̀rù rẹ̀ máa bà ọ́. Òun nìkan ni kí ọ̀rọ̀ rẹ̀ máa pá ọ láyà.

14 Yóo di ibi-mímọ́ ati òkúta ìdìgbòlù, ati àpáta tí ó ń mú kí eniyan kọsẹ̀, fún ilẹ̀ Israẹli mejeeji. Yóo di ẹ̀bìtì ati tàkúté fún àwọn ará Jerusalẹmu.

15 Ọ̀pọ̀ eniyan ni yóo kọsẹ̀ níbẹ̀; wọn yóo ṣubú, wọn yóo sì fọ́ wẹ́wẹ́. Tàkúté yóo mú wọn, ọwọ́ yóo sì tẹ̀ wọ́n.”

Ìkìlọ̀ nípa Bíbá Òkú Sọ̀rọ̀

16 Di ẹ̀rí náà, fi èdìdì di ẹ̀kọ́ náà láàrin àwọn ọmọ ẹ̀yìn mi.

17 N óo dúró de OLUWA ẹni tí ó fojú pamọ́ fún ilé Jakọbu, n óo sì ní ìrètí ninu rẹ̀.

18 Ẹ wò ó! Èmi ati àwọn ọmọ tí OLUWA fún mi, a wà fún àmì ati ìyanu ní Israẹli láti ọ̀dọ̀ OLUWA àwọn ọmọ ogun, tí ń gbé orí òkè Sioni.

19 Nígbà tí wọ́n bá wí fun yín pé kí ẹ lọ wádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ àwọn àjẹ́ ati àwọn abókùúsọ̀rọ̀ tí wọn ń jẹ ẹnu wúyẹ́-wúyẹ́. Ṣé kò yẹ kí orílẹ̀-èdè wádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ Ọlọrun wọn? Ṣé lọ́dọ̀ òkú ni ó ti yẹ kí alààyè ti máa wádìí ọ̀rọ̀?

20 Ẹ lọ wádìí ninu ẹ̀kọ́ mímọ́ ati ẹ̀rí. Bí ẹnìkan bá sọ irú ọ̀rọ̀ yìí, kò sí òye ìmọ́lẹ̀ níbẹ̀.

Àkókò Ìṣòro

21 Wọn yóo kọjá lọ lórí ilẹ̀ náà ninu ìnira ati ebi; nígbà tí ebi bá pa wọ́n, wọn yóo máa kanra, wọn óo gbé ojú wọn sókè, wọn óo sì gbé ọba ati Ọlọrun wọn ṣépè.

22 Wọn óo bojú wo ilẹ̀, kìkì ìdààmú ati òkùnkùn ati ìṣúdudu ati ìnira ni wọn óo rí. A óo sì sọ wọ́n sinu òkùnkùn biribiri.

Categories
AISAYA

AISAYA 9

Ọba Lọ́la

1 Ṣugbọn kò ní sí ìṣúdudu fún ẹni tí ó wà ninu ìnira. Ní ìgbà àtijọ́, ó sọ ilẹ̀ Sebuluni ati ilẹ̀ Nafutali di yẹpẹrẹ, ṣugbọn nígbà ìkẹyìn yóo ṣe ilẹ̀ àwọn tí ó ń gbé apá ọ̀nà òkun lógo, títí lọ dé òdìkejì odò Jọdani, ati Galili níbi tí àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè mìíràn ń gbé.

2 Àwọn tí ń rìn ninu òkùnkùn ti rí ìmọ́lẹ̀ ńlá.

Ìmọ́lẹ̀ sì ti tàn sí àwọn tí ń gbé ninu òkùnkùn biribiri.

3 Ó ti bukun orílẹ̀-èdè náà.

Ó ti fi kún ayọ̀ wọn;

wọ́n ń yọ̀ níwájú rẹ̀, bí ayọ̀ ìgbà ìkórè.

Bí inú àwọn eniyan ti máa ń dùn nígbà tí wọ́n bá ń pín ìkógun.

4 Nítorí pé ó ti ṣẹ́ àjàgà tí ó wọ̀ wọ́n lọ́rùn,

ati ọ̀pá tí wọn fí ń ru ẹrù sí èjìká,

ati kùmọ̀ àwọn tí ń fìyà jẹ wọ́n.

Ó ti ṣẹ́ wọn, bí ìgbà tí ó ṣẹ́ ti àwọn ará Midiani.

5 Gbogbo bàtà àwọn ológun, tí ń kilẹ̀ lójú ogun,

ati gbogbo ẹ̀wù tí wọ́n ti yí mọ́lẹ̀ ninu ẹ̀jẹ̀ ni a óo dáná sun,

iná yóo sì jó wọn run.

6 Nítorí a bí ọmọ kan fún wa,

a fún wa ní ọmọkunrin kan.

Òun ni yóo jọba lórí wa.

A óo máa pè é ní Ìyanu, Olùdámọ̀ràn,

Ọlọrun alágbára, Baba ayérayé,

Ọmọ-Aládé alaafia.

7 Ìjọba rẹ̀ yóo máa tóbi sí i,

alaafia kò sì ní lópin ní ìjọba rẹ̀ lórí ìtẹ́ Dafidi.

Yóo fìdí rẹ̀ múlẹ̀,

yóo sì gbé e ró pẹlu ẹ̀tọ́ ati òdodo,

láti ìgbà yìí lọ, títí ayérayé.

Ìtara OLUWA àwọn ọmọ ogun ni yóo ṣe èyí

OLUWA yóo Jẹ Israẹli Níyà

8 OLUWA ranṣẹ ìdájọ́ sí Jakọbu,

àní, sórí àwọn ọmọ Israẹli.

9 Gbogbo eniyan ni yóo mọ̀,

àwọn ará Efuraimu ati àwọn ará Samaria,

àwọn tí wọn ń fọ́nnu pẹlu ìgbéraga pé:

10 Ṣé bíríkì ni wọ́n fi kọ́ àwọn ilé tí ó wó lulẹ̀?

Òkúta gbígbẹ́ ni a óo fi tún wọn kọ́.

Igi sikamore ni a fi kọ́ èyí tí wọ́n dà wó,

ṣugbọn igi kedari dáradára ni a óo lò dípò wọn.

11 Nítorí náà OLUWA ti gbé ọ̀tá dìde sí wọn:

Ó ti rú àwọn ọ̀tá wọn sókè sí wọn:

12 Àwọn ará Siria láti ìhà ìlà oòrùn,

ati àwọn ará Filistia láti ìhà ìwọ̀ oòrùn;

wọn óo gbé Israẹli mì.

Sibẹsibẹ inú OLUWA kò rọ̀,

bẹ́ẹ̀ ni kò dá ọwọ́ ìjà rẹ̀ dúró.

13 Sibẹsibẹ àwọn ọmọ Israẹli kò pada sí ọ̀dọ̀ ẹni tí ó jẹ wọ́n níyà,

bẹ́ẹ̀ ni wọn kò wá OLUWA àwọn ọmọ-ogun.

14 Nítorí náà, OLUWA yóo fi ìyà jẹ Israẹli.

Ní ọjọ́ kan ṣoṣo, yóo gé Israẹli lórí ati nírù.

15 Àwọn àgbààgbà ati àwọn ọlọ́lá wọn ni orí,

àwọn wolii tí ń kọ́ àwọn eniyan ní ẹ̀kọ́ èké sì ni ìrù

16 Àwọn tí ń darí àwọn eniyan wọnyi ń ṣì wọ́n lọ́nà ni,

àwọn tí wọn ń tọ́ sọ́nà sì ń já sinu ìparun.

17 Nítorí náà, OLUWA kò láyọ̀ lórí àwọn ọdọmọkunrin wọn,

àánú àwọn aláìníbaba ati àwọn opó wọn kò sì ṣe é

nítorí pé aṣebi ni gbogbo wọn, wọn kò sì mọ Ọlọrun,

ọ̀rọ̀ burúkú ni wọ́n sì ń fi ẹnu wọn sọ.

Sibẹsibẹ inú OLUWA kò rọ̀,

bẹ́ẹ̀ ni kò dá ọwọ́ ìjà rẹ̀ dúró.

18 Ìwà burúkú wọn ń jó bí iná,

tí ń jó ẹ̀gún wẹ́wẹ́ ati ẹ̀gún ọ̀gàn.

Ó ń jó bíi igbó ńlá, ó sì ń yọ èéfín sókè lálá.

19 Nítorí ibinu OLUWA àwọn ọmọ ogun, ilẹ̀ náà jóná,

àwọn eniyan ibẹ̀ dàbí èpò tí a dà sinu iná

ẹnikẹ́ni kò sì dá ẹnìkejì rẹ̀ sí.

20 Wọ́n ń já nǹkan gbà lọ́tùn-ún, wọ́n ń jẹ ẹ́,

sibẹ ebi ń pa wọ́n.

Wọ́n ń jẹ àjẹrun lósì,

sibẹ wọn kò yó,

àwọn eniyan sì ń pa ara wọn jẹ.

21 Àwọn ará Manase ń bá àwọn ará Efuraimu jà,

bẹ́ẹ̀ ni àwọn ará Efuraimu náà ń bá àwọn ará Manase jà.

Àwọn mejeeji wá dojú ìjà kọ Juda.

Sibẹsibẹ inú OLUWA kò rọ̀,

bẹ́ẹ̀ ni kò dáwọ́ ìjà rẹ̀ dúró.