Categories
ẸKISODU

ẸKISODU 9

1 Ọlọrun tún sọ fún Mose pé kí ó wọlé tọ Farao lọ, kí ó sì sọ fún un pé kí ó gbọ́ ohun tí òun OLUWA Ọlọrun àwọn Heberu wí, kí ó jẹ́ kí àwọn eniyan òun lọ sìn òun.

2 Ati pé, bí ó bá kọ̀, tí kò jẹ́ kí wọ́n lọ,

3 àjàkálẹ̀ àrùn yóo ti ọwọ́ òun OLUWA wá sórí gbogbo ẹran ọ̀sìn rẹ̀ tí wọ́n wà ní pápá, ati àwọn ẹṣin rẹ̀, ati àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, ati àwọn ràkúnmí rẹ̀, ati àwọn agbo mààlúù rẹ̀, ati àwọn agbo aguntan rẹ̀.

4 Ó ní, Ṣugbọn òun yóo ya àwọn ẹran ọ̀sìn àwọn ọmọ Israẹli sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn ẹran ọ̀sìn àwọn ará Ijipti, ẹyọ kan ṣoṣo kò ní kú ninu gbogbo àwọn ẹran tíí ṣe ti àwọn ọmọ Israẹli.

5 OLUWA bá dá àkókò kan, ó ní, “Ní ọ̀la ni èmi OLUWA, yóo ṣe ohun tí mo wí yìí ní ilẹ̀ Ijipti.”

6 Nígbà tí ó di ọjọ́ keji OLUWA ṣe bí ó ti wí; gbogbo àwọn ẹran ọ̀sìn àwọn ará Ijipti kú, ṣugbọn ẹyọ kan ṣoṣo kò kú ninu ẹran ọ̀sìn àwọn ọmọ Israẹli.

7 Farao bá ranṣẹ lọ wo àwọn ẹran ọ̀sìn àwọn ọmọ Israẹli, ó sì rí i pé ẹyọ kan kò kú ninu wọn. Sibẹsibẹ ọkàn Farao le, kò sì jẹ́ kí àwọn eniyan náà lọ.

8 OLUWA sọ fún Mose ati Aaroni pé kí wọn bu ẹ̀kúnwọ́ eérú bíi mélòó kan ninu ẹbu, kí Mose dà á sí ojú ọ̀run lójú Farao,

9 yóo sì di eruku lẹ́búlẹ́bú lórí gbogbo ilẹ̀ Ijipti, yóo di oówo tí yóo máa di egbò lára eniyan ati ẹranko, ní gbogbo ilẹ̀ Ijipti.

10 Mose ati Aaroni bá bu eérú ninu ẹbu, wọ́n dúró níwájú Farao. Mose da eérú náà sókè sí ojú ọ̀run, eérú náà bá di oówo tí ń di egbò lára eniyan ati ẹranko.

11 Àwọn pidánpidán kò lè dúró níwájú Mose, nítorí pe oówo bo àwọn náà ati gbogbo àwọn eniyan ilẹ̀ Ijipti.

12 Ṣugbọn OLUWA mú kí ọkàn Farao le, kò sì gbọ́ tiwọn, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti sọ fún Mose.

13 OLUWA tún sọ fún Mose pé kí ó dìde ní òwúrọ̀ kutukutu, kí ó lọ siwaju Farao, kí ó sì sọ fún un pé kí ó gbọ́ ohun tí òun OLUWA Ọlọrun àwọn Heberu wí, kí ó jẹ́ kí àwọn eniyan òun lọ sin òun.

14 Nítorí pé lọ́tẹ̀ yìí, òun óo da gbogbo àjàkálẹ̀ àrùn òun bo Farao gan-an, ati àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀, ati àwọn eniyan rẹ̀, kí ó lè mọ̀ pé kò sí ẹni tí ó dàbí òun OLUWA ní gbogbo ayé.

15 Kí ó ranti pé, bí òun OLUWA ti nawọ́ ìyà sí òun ati àwọn eniyan rẹ̀, tí òun sì ti da àjàkálẹ̀ àrùn bò wọ́n; òun ìbá ti pa wọ́n run kúrò lórí ilẹ̀ ayé,

16 ṣugbọn ìdí pataki tí òun fi jẹ́ kí wọ́n wà láàyè ni láti fi agbára òun hàn Farao, kí wọ́n lè máa ròyìn orúkọ òun OLUWA káàkiri gbogbo ayé.

17 Ó ní Farao sì tún ń gbé ara rẹ̀ ga sí àwọn eniyan òun, kò jẹ́ kí wọ́n lọ.

18 OLUWA ní, “Wò ó, níwòyí ọ̀la, n óo da yìnyín bo ilẹ̀, irú èyí tí kò sí ní ilẹ̀ Ijipti rí, láti ọjọ́ tí wọ́n ti tẹ̀ ẹ́ dó títí di òní yìí.

19 Nítorí náà, yára ranṣẹ lọ kó gbogbo àwọn ẹran rẹ tí wọ́n wà ninu pápá síbi ìpamọ́, nítorí pé yìnyín yóo rọ̀ sórí eniyan ati ẹranko tí ó bá wà ní pápá, tí wọn kò bá kó wọlé, gbogbo wọn ni yóo sì kú.”

20 Nítorí náà gbogbo àwọn tí wọ́n bẹ̀rù ọ̀rọ̀ OLUWA ninu àwọn iranṣẹ Farao pe àwọn ẹrú wọn wálé, wọ́n sì kó àwọn ẹran ọ̀sìn wọn wálé pẹlu.

21 Ṣugbọn àwọn tí wọn kò ka ọ̀rọ̀ OLUWA sí fi àwọn ẹrú ati àwọn ohun ọ̀sìn wọn sílẹ̀ ninu pápá.

22 OLUWA sọ fún Mose pé, “Na ọwọ́ rẹ sójú ọ̀run, kí yìnyín lè bọ́ kí ó sì bo ilẹ̀ Ijipti, ati eniyan, ati ẹranko, ati gbogbo ewéko inú ìgbẹ́.”

23 Mose bá na ọ̀pá rẹ̀ sójú ọ̀run, Ọlọrun sì da ààrá ati yìnyín ati iná bo ilẹ̀, Ọlọrun sì rọ̀jò yìnyín sórí ilẹ̀ Ijipti.

24 Yìnyín ń bọ́, mànàmáná sì ń kọ yànràn ninu yìnyín náà. Yìnyín náà pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́; kò tíì sí irú rẹ̀ rí ní gbogbo ilẹ̀ Ijipti láti ìgbà tí ó ti di orílẹ̀-èdè.

25 Gbogbo ohun tí ó wà ninu oko ní gbogbo ilẹ̀ Ijipti ni yìnyín náà dà lulẹ̀, ati eniyan ati ẹranko; o sì wó gbogbo àwọn ohun ọ̀gbìn oko ati gbogbo igi lulẹ̀.

26 Àfi ilẹ̀ Goṣeni, níbi tí àwọn ọmọ Israẹli ń gbé nìkan ni yìnyín yìí kò dé.

27 Farao bá ranṣẹ pe Mose ati Aaroni, ó sọ fún wọn pé, “Mo ti dẹ́ṣẹ̀ nisinsinyii; OLUWA jàre, èmi ati àwọn eniyan mi ni a jẹ̀bi.

28 Ẹ bẹ OLUWA fún mi nítorí pé yìnyín ati ààrá yìí tó gẹ́ẹ́, n óo jẹ́ kí ẹ lọ, n kò ní da yín dúró mọ́.”

29 Mose bá dá Farao lóhùn pé, “Bí mo bá ti jáde kúrò ninu ìlú n óo gbadura sí OLUWA, ààrá kò ní sán mọ́, bẹ́ẹ̀ ni yìnyín kò ní bọ́ mọ́, kí o lè mọ̀ pé, ti OLUWA ni ilẹ̀.

30 Ṣugbọn mo mọ̀ pé ìwọ ati àwọn ẹmẹ̀wà rẹ kò bẹ̀rù OLUWA Ọlọrun.”

31 Gbogbo ọ̀gbọ̀ ati ọkà Baali tí ó wà lóko ni ó ti bàjẹ́ patapata, nítorí pé ọkà baali ati ọ̀gbọ̀ náà ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí so ni.

32 Ṣugbọn ọkà alikama ati ọkà ria kò bàjẹ́, nítorí pé wọn kò tètè hù.

33 Mose bá kúrò lọ́dọ̀ Farao, ó jáde kúrò ní ìlú; ó gbadura sí OLUWA, ààrá tí ń sán ati yìnyín tí ń bọ́ sì dáwọ́ dúró, òjò náà sì dá lórí ilẹ̀.

34 Ṣugbọn nígbà tí Farao rí i pé òjò ti dá, ati pé yìnyín ati ààrá ti dáwọ́ dúró, ó tún dẹ́ṣẹ̀, ọkàn rẹ̀ tún le, ati ti àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀.

35 Ọkàn rẹ̀ tún le, kò sì jẹ́ kí àwọn ọmọ Israẹli lọ, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti sọ láti ẹnu Mose.

Categories
ẸKISODU

ẸKISODU 10

1 OLUWA bá pe Mose, ó ní, “Wọlé tọ Farao lọ, nítorí pé mo tún ti mú ọkàn rẹ̀ le, ati ti àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀, kí n lè ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu mi láàrin wọn.

2 Kí ẹ̀yin náà sì lè sọ fún àwọn ọmọ ati àwọn ọmọ ọmọ yín, irú ohun tí mo fi ojú wọn rí, ati irú iṣẹ́ ìyanu tí mo ṣe láàrin wọn; kí ẹ lè mọ̀ pé èmi ni OLUWA.”

3 Nítorí náà, Mose ati Aaroni lọ, wọ́n sì wí fún Farao pé, “OLUWA Ọlọrun àwọn Heberu ní kí á bèèrè lọ́wọ́ rẹ pé, yóo ti pẹ́ tó tí o óo fi kọ̀ láti rẹ ara rẹ sílẹ̀ níwájú òun Ọlọrun? Ó ní, kí o jẹ́ kí àwọn eniyan òun lọ kí wọ́n lè sin òun.

4 Nítorí pé bí o bá kọ̀, tí o kò jẹ́ kí àwọn eniyan òun lọ, ó ní òun yóo mú kí eṣú wọ ilẹ̀ rẹ lọ́la.

5 Àwọn eṣú náà yóo sì bo gbogbo ilẹ̀, tóbẹ́ẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò ní rí ilẹ̀ rárá, wọn yóo sì jẹ gbogbo ohun tí ó ṣẹ́kù tí yìnyín kò pa, wọn yóo jẹ gbogbo igi rẹ tí ó wà ninu pápá oko.

6 Wọn yóo rọ́ kún gbogbo ààfin rẹ ati ilé gbogbo àwọn ẹmẹ̀wà rẹ ati ilé gbogbo àwọn ará Ijipti, àwọn eṣú náà yóo burú ju ohunkohun tí àwọn baba ati àwọn baba ńlá yín ti rí rí lọ, láti ọjọ́ tí wọ́n ti dáyé títí di òní olónìí.” Mose bá yipada kúrò níwájú Farao.

7 Àwọn ẹmẹ̀wà Farao sọ fún un pé, “Kabiyesi, ìgbà wo ni ọkunrin yìí yóo yọ wá lẹ́nu dà? Ẹ jẹ́ kí wọ́n lọ kí wọ́n lè lọ sin OLUWA Ọlọrun wọn. Àbí kò tíì hàn sí kabiyesi báyìí pé gbogbo Ijipti tí ń parun tán lọ ni?”

8 Wọ́n bá mú Mose ati Aaroni pada tọ Farao lọ. Farao ní kí wọ́n lọ sin OLUWA Ọlọrun wọn, ṣugbọn ó bèèrè pé àwọn wo gan-an ni yóo lọ?

9 Mose dáhùn pé, “Gbogbo wa ni à ń lọ, ati àgbà ati èwe; ati ọkunrin ati obinrin, ati gbogbo agbo mààlúù wa, ati gbogbo agbo ẹran wa, nítorí pé a níláti lọ ṣe àjọ̀dún kan fún OLUWA.”

10 Farao bá dáhùn, ó ní, “Kí OLUWA wà pẹlu yín bí mo bá jẹ́ kí ẹ̀yin ati àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ yín lọ. Wò ó, ète burúkú wà ní ọkàn yín.

11 N ò gbà! Ẹ̀yin ọkunrin nìkan ni kí ẹ lọ sin OLUWA; nítorí pé bẹ́ẹ̀ gan-an ni ẹ fẹ́ àbí?” Wọ́n bá lé wọn jáde kúrò níwájú Farao.

12 OLUWA bá sọ fún Mose pé, “Na ọwọ́ rẹ sórí ilẹ̀ Ijipti, kí eṣú lè tú jáde, kí wọ́n sì bo gbogbo ilẹ̀ náà, kí wọ́n jẹ gbogbo ohun ọ̀gbìn tí ó ṣẹ́kù ní ilẹ̀ náà tí yìnyín kò pa.”

13 Mose bá gbé ọ̀pá rẹ̀, ó nà án sókè, sórí gbogbo ilẹ̀ Ijipti. OLUWA bá mú kí afẹ́fẹ́ kan fẹ́ wá láti ìlà oòrùn, afẹ́fẹ́ náà fẹ́ sórí gbogbo ilẹ̀ náà, ní gbogbo ọ̀sán ati ní gbogbo òru ọjọ́ náà. Nígbà tí yóo fi di òwúrọ̀ ọjọ́ keji, afẹ́fẹ́ ti kó eṣú dé.

14 Eṣú bo gbogbo ilẹ̀ Ijipti, wọ́n sì bà sí gbogbo ilẹ̀. Wọ́n pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ó jẹ́ pé irú rẹ̀ kò sí rí, irú rẹ̀ kò sì tún tíì ṣẹlẹ̀ mọ́ láti ìgbà náà.

15 Nítorí pé wọ́n bo gbogbo ilẹ̀ patapata, tóbẹ́ẹ̀ tí gbogbo ojú ọ̀run ṣókùnkùn dudu, wọ́n sì jẹ gbogbo ewé, ati gbogbo èso tí ń bẹ lórí igi, ati koríko tí ó ṣẹ́kù tí yìnyín kò pa. Ẹyọ ewé kan kò kù lórí igi, tabi koríko, tabi ohun ọ̀gbìn kan ninu oko, jákèjádò ilẹ̀ Ijipti.

16 Farao bá yára pe Mose ati Aaroni, ó ní, “Mo ti ṣẹ̀ sí OLUWA Ọlọrun yín ati sí ẹ̀yin pàápàá.

17 Ẹ jọ̀wọ́, ẹ dárí ẹ̀ṣẹ̀ mi jì mí, ẹ bá mi bẹ OLUWA Ọlọrun yín ní ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo péré yìí, kí ó jọ̀wọ́ mú ikú yìí kúrò lọ́dọ̀ mi.”

18 Mose bá jáde kúrò níwájú Farao, ó lọ gbadura sí OLUWA.

19 OLUWA bá yí afẹ́fẹ́ líle ìwọ̀ oòrùn pada, ó bá bẹ̀rẹ̀ sí fẹ́ àwọn eṣú náà lọ sí inú Òkun Pupa, ẹyọ eṣú kan ṣoṣo kò sì kù mọ́ ní gbogbo ilẹ̀ Ijipti.

20 Ṣugbọn OLUWA tún mú kí ọkàn Farao le, kò sì jẹ́ kí àwọn ọmọ Israẹli lọ.

21 OLUWA bá sọ fún Mose pé, “Gbé ọwọ́ rẹ sókè sí ojú ọ̀run, kí òkùnkùn lè ṣú bo gbogbo ilẹ̀ Ijipti, òkùnkùn biribiri tí eniyan fẹ́rẹ̀ lè dì mú.”

22 Mose bá gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè sí ojú ọ̀run, òkùnkùn biribiri sì ṣú bo gbogbo ilẹ̀ Ijipti fún odidi ọjọ́ mẹta.

23 Wọn kò lè rí ara wọn, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò sì dìde kúrò níbi tí ó wà fún ọjọ́ mẹta. Ṣugbọn ìmọ́lẹ̀ wà ní gbogbo ibi tí àwọn ọmọ Israẹli ń gbé.

24 Farao bá tún ranṣẹ lọ pe Mose, ó ní, “Ẹ lọ sin Ọlọrun yín, ẹ máa kó àwọn ọmọ yín lọ pẹlu, ṣugbọn ẹ fi agbo aguntan yín ati agbo ẹran yín sílẹ̀.”

25 Mose dáhùn pé, “O níláti jẹ́ kí á kó ẹran tí a óo fi rúbọ lọ́wọ́, ati èyí tí a óo fi rúbọ sísun sí OLUWA Ọlọrun wa.

26 A níláti kó àwọn ẹran ọ̀sìn wa lọ, a kò ní fi ohunkohun sílẹ̀ lẹ́yìn, nítorí pé ninu wọn ni a óo ti mú láti fi rúbọ sí OLUWA Ọlọrun wa; a kò sì tíì mọ ohun tí a óo fi rúbọ, àfi ìgbà tí a bá débẹ̀.”

27 Ṣugbọn OLUWA Ọlọrun mú kí ọkàn Farao le, kò sì jẹ́ kí wọ́n lọ.

28 Farao bá lé Mose, ó ní, “Kúrò lọ́dọ̀ mi; kí o sì ṣọ́ra rẹ gidigidi, n kò gbọdọ̀ tún rí ọ níwájú mi mọ́; ní ọjọ́ tí mo bá tún fi ojú kàn ọ́, ọjọ́ náà ni o óo kú!”

29 Mose bá dáhùn, ó ní, “Bí o ti wí gan-an ni yóo rí. N kò ní dé iwájú rẹ mọ́.”

Categories
ẸKISODU

ẸKISODU 11

Mose Kéde Ikú Àwọn Àkọ́bí

1 Nígbà tí ó yá, OLUWA sọ fún Mose pé, “Ó ku ìyọnu kan péré, tí n óo mú bá Farao ati ilẹ̀ Ijipti, lẹ́yìn náà yóo jẹ́ kí ẹ lọ. Nígbà tí ó bá gbà kí ẹ lọ, òun fúnra rẹ̀ ni yóo tì yín jáde patapata.

2 Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé kí olukuluku tọ aládùúgbò rẹ̀ lọ, ati ọkunrin ati obinrin wọn, kí wọ́n lọ tọrọ nǹkan ọ̀ṣọ́ fadaka ati ti wúrà.”

3 OLUWA jẹ́ kí àwọn eniyan Israẹli bá ojurere àwọn ará Ijipti pàdé, ati pé àwọn ará Ijipti ati àwọn ẹmẹ̀wà Farao ati àwọn eniyan rẹ̀ ka Mose kún eniyan pataki.

4 Mose bá sọ fún Farao pé, “OLUWA ní, nígbà tí ó bá di ọ̀gànjọ́ òru, òun yóo la ilẹ̀ Ijipti kọjá,

5 gbogbo àkọ́bí ní ilẹ̀ Ijipti ni yóo sì kú. Bẹ̀rẹ̀ láti orí àkọ́bí Farao, tí ó jókòó lórí ìtẹ́, títí kan àkọ́bí iranṣẹbinrin tí ń lọ ọkà, ati àkọ́bí gbogbo ẹran ọ̀sìn.

6 Ariwo ẹkún ńlá yóo sọ ní gbogbo ilẹ̀ Ijipti, irú èyí tí kò ṣẹlẹ̀ rí, tí kò sì tún ní sí irú rẹ̀ mọ́.

7 Ṣugbọn ajá kò tilẹ̀ ní gbó ẹnikẹ́ni tabi ẹran ọ̀sìn kan, jákèjádò ààrin àwọn ọmọ Israẹli; kí ẹ lè mọ̀ pé OLUWA fi ìyàtọ̀ sí ààrin àwọn ará Ijipti ati àwọn ọmọ Israẹli.

8 Gbogbo àwọn ẹmẹ̀wà rẹ wọnyi yóo sì tọ̀ mí wá, wọn yóo fi orí balẹ̀ fún mi, wọn yóo wí pé kí n máa lọ, èmi ati gbogbo àwọn eniyan mi! Lẹ́yìn náà ni n óo jáde lọ.” Mose bá fi tìbínú-tìbínú jáde kúrò níwájú Farao.

9 Lẹ́yìn náà OLUWA sọ fún Mose pé, “Farao kò ní gba ọ̀rọ̀ rẹ, kí iṣẹ́ ìyanu mi baà lè di pupọ ní ilẹ̀ Ijipti.”

10 Mose ati Aaroni ṣe gbogbo iṣẹ́ ìyanu tí wọn ṣe níwájú Farao, ṣugbọn OLUWA sì mú kí ọkàn Farao le, kò sì jẹ́ kí àwọn eniyan Israẹli lọ kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀.

Categories
ẸKISODU

ẸKISODU 12

Àjọ Ìrékọjá

1 OLUWA sọ fún Mose ati Aaroni ní ilẹ̀ Ijipti pé,

2 “Oṣù yìí ni yóo jẹ́ oṣù kinni ọdún fún yín.

3 Ẹ sọ fún gbogbo ìjọ eniyan Israẹli pé, ní ọjọ́ kẹwaa oṣù yìí, ọkunrin kọ̀ọ̀kan ninu ìdílé kọ̀ọ̀kan yóo mú ọ̀dọ́ aguntan kọ̀ọ̀kan tabi àwọ́nsìn kọ̀ọ̀kan; ọ̀dọ́ aguntan kan fún ilé kan.

4 Bí ìdílé kan bá wà tí ó kéré jù láti jẹ ẹran ọ̀dọ́ aguntan kan tán, ìdílé yìí yóo darapọ̀ mọ́ ìdílé mìíràn ní àdúgbò rẹ̀, wọn yóo sì pín ẹran tí wọ́n bá pa gẹ́gẹ́ bí iye eniyan tí ó wà ninu ìdílé mejeeji, iye eniyan tí ó bá lè jẹ àgbò kan tán ni yóo darapọ̀ láti pín ọ̀dọ́ aguntan náà.

5 Ọ̀dọ́ aguntan tabi àwọ́nsìn ewúrẹ́ náà kò gbọdọ̀ lábàwọ́n, ó lè jẹ́ àgbò tabi òbúkọ ọlọ́dún kan.

6 Wọ́n óo so ẹran wọn mọ́lẹ̀ títí di ọjọ́ kẹrinla oṣù yìí. Nígbà tí ó bá di ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà, gbogbo ìjọ eniyan Israẹli yóo pa ẹran wọn.

7 Wọn yóo mú díẹ̀ ninu ẹ̀jẹ̀ ẹran náà, wọn yóo fi kun àtẹ́rígbà ati ara òpó ìlẹ̀kùn mejeeji ilé tí wọn yóo ti jẹ ẹran náà.

8 Alẹ́ ọjọ́ náà ni kí wọ́n sun ẹran náà, kí wọ́n sì jẹ ẹ́ pẹlu burẹdi tí kò ní ìwúkàrà ninu, ati ewébẹ̀ tí ó korò bí ewúro.

9 Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ninu ẹran yìí ní tútù, tabi bíbọ̀; sísun ni kí ẹ sun ún; ati orí rẹ̀ ati ẹsẹ̀ rẹ̀, ati àwọn nǹkan inú rẹ̀.

10 Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ́ kí ó ṣẹ́kù di òwúrọ̀ ọjọ́ keji, bí ohunkohun bá ṣẹ́kù, ẹ dáná sun ún.

11 Bí ẹ ó ṣe jẹ ẹ́ nìyí: ẹ di àmùrè yín mọ́ ẹ̀gbẹ́ yín, ẹ wọ bàtà yín, ẹ mú ọ̀pá yín lọ́wọ́; ìkánjú ni kí ẹ fi jẹ ẹ́, nítorí pé oúnjẹ ìrékọjá fún OLUWA ni.

12 “Nítorí pé, ní òru ọjọ́ náà ni n óo la gbogbo ilẹ̀ Ijipti kọjá, n óo pa gbogbo àkọ́bí ilẹ̀ náà, ati ti eniyan ati ti ẹranko, n óo sì jẹ gbogbo àwọn oriṣa ilẹ̀ Ijipti níyà. Èmi ni OLUWA.

13 Ẹ̀jẹ̀ tí ẹ bá fi kun àtẹ́rígbà ìlẹ̀kùn gbogbo ilé yín ni yóo jẹ́ àmì láti fi gbogbo ibi tí ẹ bá wà hàn. Nígbà tí mo bá rí ẹ̀jẹ̀ náà, n óo re yín kọjá; n kò ní fi àjàkálẹ̀ àrùn ba yín jà láti pa yín run nígbà tí mo bá ń jẹ àwọn eniyan ilẹ̀ Ijipti níyà.

14 Ọjọ́ ìrántí ni ọjọ́ yìí yóo jẹ́ fún yín, ní ọdọọdún ni ẹ óo sì máa ṣe àjọ̀dún rẹ̀ fún OLUWA; àwọn arọmọdọmọ yín yóo sì máa ṣe àjọ̀dún yìí bí ìlànà, gẹ́gẹ́ bí ohun ìrántí títí lae.

Àjọ̀dún Àìwúkàrà

15 “Ọjọ́ meje ni ẹ óo fi jẹ burẹdi tí kò ní ìwúkàrà ninu. Láti ọjọ́ kinni ni kí ẹ ti mú gbogbo ìwúkàrà kúrò ninu ilé yín, nítorí pé bí ẹnikẹ́ni bá jẹ burẹdi tí ó ní ìwúkàrà ninu láti ọjọ́ kinni títí di ọjọ́ keje, a kò ní ka irú ẹni bẹ́ẹ̀ kún àwọn eniyan Israẹli mọ́.

16 Ní ọjọ́ kinni ati ní ọjọ́ keje, ẹ óo péjọ pọ̀ láti jọ́sìn. Ní ọjọ́ mejeeje yìí, ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ ṣiṣẹ́ rárá, àfi oúnjẹ tí ẹ óo bá jẹ nìkan ni ẹ lè sè.

17 Ẹ óo máa ṣe àjọ̀dún ìrántí àjọ àìwúkàrà, nítorí ọjọ́ yìí ni ọjọ́ tí mo ko yín jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti. Nítorí náà ẹ óo máa ṣe ìrántí ọjọ́ náà bí ìlànà ati ẹ̀yin ati àwọn arọmọdọmọ yín títí lae.

18 Láti ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kẹrinla oṣù kinni yìí títí di ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kọkanlelogun oṣù náà, burẹdi tí kò ní ìwúkàrà ni ẹ gbọdọ̀ máa jẹ.

19 Kò gbọdọ̀ sí ìwúkàrà ninu ilé yín fún ọjọ́ mejeeje, nítorí pé bí ẹnikẹ́ni bá jẹ burẹdi tí ó ní ìwúkàrà ninu, a kò ní ka irú ẹni bẹ́ẹ̀ kún àwọn eniyan Israẹli mọ́, kì báà jẹ́ àlejò tabi onílé ní ilẹ̀ náà.

20 Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ohunkohun tí ó ní ìwúkàrà ninu; ninu gbogbo ilé yín patapata, burẹdi tí kò ní ìwúkàrà ninu ni ẹ gbọdọ̀ máa jẹ.”

Àjọ Ìrékọjá Kinni

21 Mose bá pe gbogbo àwọn àgbààgbà Israẹli jọ, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ ṣa ọ̀dọ́ aguntan kọ̀ọ̀kan ní ìdílé yín kọ̀ọ̀kan, kí ẹ sì pa á fún ìrékọjá.

22 Ẹ mú ìdì ewé hisopu, kí ẹ tì í bọ ẹ̀jẹ̀ tí ẹ bá gbè sinu àwo kòtò kan, kí ẹ fi ẹ̀jẹ̀ náà kun àtẹ́rígbà ati òpó ìlẹ̀kùn mejeeji. Ẹnikẹ́ni ninu yín kò sì gbọdọ̀ jáde ninu ilé títí di òwúrọ̀ ọjọ́ keji.

23 Nítorí pé, OLUWA yóo rékọjá, yóo sì pa àwọn ará Ijipti. Ṣugbọn nígbà tí ó bá rí ẹ̀jẹ̀ lára àtẹ́rígbà ati lára òpó ẹnu ọ̀nà mejeeji, OLUWA yóo ré ẹnu ọ̀nà náà kọjá, kò sì ní jẹ́ kí apanirun wọ ilé yín láti pa yín.

24 Ẹ̀yin ati àwọn arọmọdọmọ yín, ẹ gbọdọ̀ máa pa ìlànà yìí mọ́ gẹ́gẹ́ bí òfin títí lae.

25 Nígbà tí ẹ bá sì dé ilẹ̀ tí OLUWA yóo fún yín gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ìlérí, ẹ gbọdọ̀ máa ṣe ìsìn yìí.

26 Nígbà tí àwọn ọmọ yín bá sì bi yín léèrè pé, ‘Kí ni ìtumọ̀ ìsìn yìí?’

27 ẹ óo dá wọn lóhùn pé, ‘Ẹbọ ìrékọjá OLUWA ni, nítorí pé ó ré ilé àwọn eniyan Israẹli kọjá ní Ijipti, nígbà tí ó ń pa àwọn ará Ijipti, ṣugbọn ó dá àwọn ilé wa sí.’ ”

Àwọn eniyan Israẹli wólẹ̀, wọ́n sì sin OLUWA.

28 Wọ́n bá lọ, wọ́n sì ṣe bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose ati Aaroni.

Ikú Àwọn Àkọ́bí

29 Nígbà tí ó di ọ̀gànjọ́ òru, OLUWA lu gbogbo àwọn àkọ́bí ilẹ̀ Ijipti pa, ó bẹ̀rẹ̀ láti orí àrẹ̀mọ ọba Farao tí ó wà lórí ìtẹ́, títí kan àkọ́bí ẹrú tí ó wà ninu ọgbà ẹ̀wọ̀n, ati àkọ́bí gbogbo ẹran ọ̀sìn.

30 Farao bá dìde ní ọ̀gànjọ́ òru, òun ati gbogbo àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀, ati gbogbo àwọn ará Ijipti. Igbe ẹkún ńlá sì sọ ní gbogbo ilẹ̀ Ijipti, nítorí pé kò sí ẹyọ ilé kan tí eniyan kò ti kú.

31 Farao bá ranṣẹ pe Mose ati Aaroni ní òru ọjọ́ náà, ó ní, “Ẹ gbéra, ẹ máa lọ, ẹ jáde kúrò láàrin àwọn eniyan mi, ati ẹ̀yin ati àwọn eniyan Israẹli, ẹ lọ sin OLUWA yín bí ẹ ti wí.

32 Ẹ máa kó àwọn agbo mààlúù yín lọ, ati agbo aguntan yín, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti wí. Ẹ máa lọ; ṣugbọn ẹ súre fún èmi náà!”

33 Àwọn ará Ijipti bá ń kán àwọn eniyan náà lójú láti tètè máa lọ. Wọ́n ní bí wọn kò bá tètè lọ, gbogbo àwọn ni àwọn yóo di òkú.

34 Àwọn eniyan náà bá mú àkàrà tí wọ́n ti pò, ṣugbọn tí wọn kò tíì fi ìwúkàrà sí, wọ́n sì fi aṣọ so ọpọ́n ìpòkàrà wọn, wọ́n gbé e kọ́ èjìká.

35 Àwọn eniyan náà ṣe bí Mose ti sọ fún wọn, olukuluku wọn ti tọ àwọn ará Ijipti lọ, wọ́n ti tọrọ ohun ọ̀ṣọ́ fadaka ati ti wúrà ati aṣọ.

36 OLUWA sì jẹ́ kí wọ́n bá ojurere àwọn ará Ijipti pàdé, gbogbo ohun tí wọ́n tọrọ pátá ni àwọn ará Ijipti fún wọn. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn eniyan Israẹli ṣe, tí wọ́n sì fi kó ohun ọ̀ṣọ́ àwọn ará Ijipti lọ.

Àwọn Ọmọ Israẹli Jáde Kúrò ní Ijipti

37 Àwọn eniyan Israẹli gbéra, wọ́n rìn láti Ramesesi lọ sí Sukotu. Iye àwọn eniyan náà tó ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ (600,000) ọkunrin, láìka àwọn obinrin ati àwọn ọmọde.

38 Ọpọlọpọ àwọn mìíràn ni wọ́n bá wọn lọ, pẹlu ọpọlọpọ ẹran ọ̀sìn ati agbo aguntan ati agbo mààlúù.

39 Wọ́n mú ìyẹ̀fun tí wọ́n ti pò ní ilẹ̀ Ijipti, wọ́n fi ṣe burẹdi tí kò ní ìwúkàrà, nítorí pé lílé ni àwọn ará Ijipti lé wọn jáde, wọn kò sì lè dúró mú oúnjẹ mìíràn lọ́wọ́.

40 Àkókò tí àwọn ọmọ Israẹli gbé ní ilẹ̀ Ijipti jẹ́ irinwo ọdún ó lé ọgbọ̀n (430).

41 Ọjọ́ tí ó pé irinwo ọdún ó lé ọgbọ̀n (430) gééré, tí wọ́n ti dé ilẹ̀ Ijipti; ni àwọn eniyan OLUWA jáde kúrò níbẹ̀.

42 Ṣíṣọ́ ni OLUWA ń ṣọ́ wọn ní gbogbo òru ọjọ́ náà títí ó fi kó wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti. Àwọn eniyan Israẹli ya alẹ́ ọjọ́ náà sọ́tọ̀ fún OLUWA, láti ìrandíran wọn. Ní ọdọọdún ni wọ́n máa ń ṣọ́nà ní òru ní ìrántí òru àyájọ́ ọjọ́ náà.

Àwọn Òfin Àjọ Ìrékọjá

43 OLUWA sọ fún Mose ati Aaroni pé, “Òfin àjọ ìrékọjá nìwọ̀nyí: àlejò kankan kò gbọdọ̀ ba yín jẹ oúnjẹ àjọ ìrékọjá.

44 Ṣugbọn àwọn ẹrú tí ẹ fi owó rà, tí ẹ sì kọ ní ilà abẹ́ lè bá yín jẹ ẹ́.

45 Àlejò kankan tabi alágbàṣe kò gbọdọ̀ ba yín jẹ ẹ́.

46 Ilé tí ẹ bá ti se oúnjẹ yìí ni ẹ ti gbọdọ̀ jẹ gbogbo rẹ̀, ẹ kò gbọdọ̀ mú ninu ẹran rẹ̀ jáde, ẹ kò sì gbọdọ̀ fọ́ egungun rẹ̀.

47 Gbogbo ìjọ eniyan Israẹli ni ó gbọdọ̀ ṣe ìrántí ọjọ́ yìí.

48 Bí àlejò kan bá wọ̀ sí ilé yín, tí ó bá sì fẹ́ bá yín ṣe àjọ̀dún àjọ ìrékọjá, ó gbọdọ̀ kọ gbogbo àwọn ọkunrin inú ìdílé rẹ̀ ní ilà abẹ́, lẹ́yìn náà, ó lè ba yín ṣe àjọ̀dún náà, òun náà yóo dàbí olùgbé ilẹ̀ náà, ṣugbọn ẹnikẹ́ni tí kò bá kọ ilà abẹ́ kò gbọdọ̀ jẹ ninu àjọ ìrékọjá náà.

49 Ati ẹ̀yin, ati àlejò tí ń gbé ààrin yín, òfin kan ṣoṣo ni ó de gbogbo yín.”

50 Gbogbo àwọn eniyan Israẹli bá ṣe bí àṣẹ tí OLUWA pa fún Mose ati Aaroni.

51 Ní ọjọ́ yìí gan-an ni OLUWA mú àwọn ẹ̀yà Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti.

Categories
ẸKISODU

ẸKISODU 13

Yíya Àwọn Àkọ́bí sí Mímọ́

1 OLUWA sọ fún Mose pé,

2 “Ya gbogbo àwọn àkọ́bí sí mímọ́ fún mi, ohunkohun tí ó bá ti jẹ́ àkọ́bí láàrin àwọn eniyan Israẹli, kì báà ṣe ti eniyan, tabi ti ẹranko, tèmi ni wọ́n.”

Àjọ Àìwúkàrà

3 Mose sọ fún àwọn eniyan náà pé, “Ẹ ranti ọjọ́ òní tíí ṣe ọjọ́ tí ẹ jáde láti ilẹ̀ Ijipti, láti inú ìgbèkùn, nítorí pé pẹlu ipá ni OLUWA fi mu yín jáde kúrò níbẹ̀, ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ jẹ burẹdi tí wọ́n fi ìwúkàrà sí.

4 Òní ni ọjọ́ pé tí ẹ óo jáde kúrò ní Ijipti, ninu oṣù Abibu.

5 Nígbà tí Ọlọrun bá mu yín wá sí ilẹ̀ àwọn ará Kenaani ati ti àwọn ará Hiti, ati ti àwọn ará Amori, ati ti àwọn ará Hifi, ati ti àwọn ará Jebusi, tí ó ti búra fún àwọn baba yín pé òun yóo fi fún yín, tí ó kún fún wàrà ati oyin, ẹ óo máa ṣe ìsìn yìí ninu oṣù yìí lọdọọdun.

6 Ọjọ́ meje ni ẹ óo fi jẹ burẹdi tí kò ní ìwúkàrà, ní ọjọ́ keje ẹ óo pe àpèjọ kan fún OLUWA láti ṣe àjọ̀dún.

7 Láàrin ọjọ́ meje tí ẹ óo fi jẹ burẹdi tí kò ní ìwúkàrà, a kò gbọdọ̀ rí burẹdi tí ó ní ìwúkàrà lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni ninu yín, kò sì gbọdọ̀ sí ìwúkàrà ní gbogbo agbègbè yín.

8 Kí olukuluku wí fún ọmọ rẹ̀ ní ọjọ́ náà pé, ‘Nítorí ohun tí OLUWA ṣe fún mi, nígbà tí ó mú mi jáde láti ilẹ̀ Ijipti wá, ni mo fi ń ṣe ohun tí mò ń ṣe yìí.’

9 Kí ó jẹ́ àmì ní ọwọ́ rẹ, ati ohun ìrántí láàrin ojú rẹ, kí òfin OLUWA lè wà ní ẹnu rẹ, nítorí pé pẹlu ipá ni OLUWA fi mú ọ jáde láti ilẹ̀ Ijipti wá.

10 Nítorí náà, ẹ máa ṣe ìrántí ìlànà yìí ní àkókò rẹ̀ ní ọdọọdún.

Àwọn Àkọ́bí

11 “Nígbà tí OLUWA bá mu yín dé ilẹ̀ àwọn ará Kenaani, gẹ́gẹ́ bí ó ti búra fún ẹ̀yin ati àwọn baba yín, tí ó bá sì fún yín ní ilẹ̀ náà,

12 gbogbo ohun tí ó bá ti jẹ́ àkọ́bí ni ẹ gbọdọ̀ yà sọ́tọ̀ fún OLUWA. Gbogbo àkọ́bí ẹran ọ̀sìn yín tí ó bá jẹ́ akọ, ti OLUWA ni.

13 Ẹ gbọdọ̀ fi ọ̀dọ́ aguntan ra gbogbo àkọ́bí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ yín pada, bí ẹ kò bá sì fẹ́ rà wọ́n pada, dandan ni pé kí ẹ lọ́ wọn lọ́rùn pa. Ẹ gbọdọ̀ ra gbogbo àkọ́bí yín tí wọ́n jẹ́ ọkunrin pada.

14 Ní ọjọ́ iwájú bí àwọn ọmọkunrin yín bá bèèrè ìtumọ̀ ohun tí ẹ̀ ń ṣe lọ́wọ́ yín, ohun tí ẹ óo wí fún wọn ni pé, ‘Pẹlu ipá ni OLUWA fi mú wa jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti, níbi tí a ti wà ní ìgbèkùn rí.

15 Nítorí pé nígbà tí Farao ṣe orí kunkun, tí ó sì kọ̀, tí kò jẹ́ kí á lọ, OLUWA pa gbogbo àwọn àkọ́bí ilẹ̀ Ijipti, ti eniyan ati ti ẹranko. Ìdí nìyí tí mo fi ń fi àkọ́bí ẹran ọ̀sìn mi, tí ó bá jẹ́ akọ rúbọ sí OLUWA, tí mo sì fi ń ra àwọn àkọ́bí mi ọkunrin pada.’

16 Ẹ fi ṣe àmì sí ọwọ́ yín, ati ìgbàjú sí iwájú yín, nítorí pé pẹlu ipá ni OLUWA fi mú wa jáde ní ilẹ̀ Ijipti.”

Ọ̀wọ̀n Ìkùukùu ati Ọ̀wọ̀n Iná

17 Nígbà tí Farao gbà pé kí àwọn ọmọ Israẹli máa lọ, Ọlọrun kò mú wọn gba ọ̀nà ilẹ̀ àwọn ará Filistia, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀nà ibẹ̀ yá, nítorí pé Ọlọrun rò ó ninu ara rẹ̀ pé, “Kí àwọn eniyan yìí má lọ yí ọkàn pada, bí àwọn kan bá gbógun tì wọ́n lójú ọ̀nà, kí wọ́n sì sá pada sí ilẹ̀ Ijipti.”

18 Ṣugbọn Ọlọrun mú kí wọ́n gba ọ̀nà aṣálẹ̀, ní agbègbè Òkun Pupa, àwọn eniyan Israẹli sì jáde láti ilẹ̀ Ijipti pẹlu ìmúrasílẹ̀ ogun.

19 Mose kó egungun Josẹfu lọ́wọ́ nígbà tí wọ́n ń lọ, nítorí pé Josẹfu ti mú kí àwọn ọmọ Israẹli jẹ́jẹ̀ẹ́, ó ní, “Ọlọrun yóo gbà yín là, nígbà tí ó bá yá tí ẹ̀ bá ń lọ, ẹ kó egungun mi lọ́wọ́ lọ.”

20 Wọ́n gbéra láti Sukotu, wọ́n pàgọ́ sí Etamu létí aṣálẹ̀.

21 OLUWA sì ń lọ níwájú wọn ní ọ̀sán ninu ọ̀wọ̀n ìkùukùu láti máa fi ọ̀nà hàn wọ́n, ati ní òru, ninu ọ̀wọ̀n iná láti máa fún wọn ní ìmọ́lẹ̀ kí wọ́n lè máa rìn ní ọ̀sán ati ní òru.

22 Ọ̀wọ̀n ìkùukùu kò fi ìgbà kan kúrò níwájú àwọn eniyan náà ní ọ̀sán, bẹ́ẹ̀ náà sì ni ọ̀wọ̀n iná ní òru.

Categories
ẸKISODU

ẸKISODU 14

Líla Òkun Pupa Kọjá

1 OLUWA bá rán Mose, ó ní,

2 “Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé kí wọ́n yipada, kí wọ́n sì pàgọ́ siwaju Pi Hahirotu, láàrin Migidoli ati Òkun Pupa, níwájú Baali Sefoni; ẹ pàgọ́ yín siwaju rẹ̀ lẹ́bàá òkun.

3 Nítorí Farao yóo wí pé, ‘Ilẹ̀ ti ká àwọn eniyan Israẹli mọ́, aṣálẹ̀ sì ti sé wọn mọ́.’

4 N óo tún mú kí ọkàn Farao le, yóo lépa yín, n óo sì gba ògo lórí Farao ati ogun rẹ̀, àwọn ará Ijipti yóo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA.” Àwọn eniyan Israẹli sì ṣe bí OLUWA ti wí.

5 Nígbà tí wọ́n sọ fún Farao, ọba Ijipti, pé àwọn ọmọ Israẹli ti sálọ, èrò òun ati àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ nípa àwọn eniyan náà yipada. Wọ́n wí láàrin ara wọn pé, “Irú kí ni a ṣe yìí, tí a jẹ́ kí àwọn eniyan wọnyi lọ mọ́ wa lọ́wọ́, tí a kò jẹ́ kí wọ́n ṣì máa sìn wá?”

6 Nítorí náà Farao ní kí wọ́n tọ́jú kẹ̀kẹ́ ogun òun, ó sì kó àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jọ.

7 Ó ṣa ẹgbẹta (600) kẹ̀kẹ́ ogun tí ó dára, ati àwọn kẹ̀kẹ́ ogun ilẹ̀ Ijipti yòókù, ó sì yan àwọn olórí ogun tí yóo máa ṣe àkóso wọn.

8 OLUWA mú ọkàn Farao, ọba Ijipti le, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí lépa àwọn ọmọ Israẹli bí wọ́n ti ń lọ tìgboyà-tìgboyà.

9 Àwọn ará Ijipti ń lé wọn lọ, pẹlu gbogbo ẹṣin ati kẹ̀kẹ́ ogun Farao, ati gbogbo àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀, ati gbogbo àwọn jagunjagun rẹ̀, wọ́n bá wọn níbi tí wọ́n pàgọ́ sí lẹ́bàá òkun, lẹ́bàá Pi Hahirotu ni òdìkejì Baali Sefoni.

10 Nígbà tí Farao súnmọ́ àwọn ọmọ Israẹli, tí àwọn ọmọ Israẹli gbé ojú sókè tí wọ́n rí àwọn ará Ijipti tí wọn ń bọ̀ lẹ́yìn wọn; ẹ̀rù bà wọ́n gidigidi. Wọ́n kígbe sí OLUWA;

11 wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ sí Mose pé, “Ṣé kò sí ibojì ní Ijipti ni o fi kó wa kúrò láti wá kú sí ààrin aṣálẹ̀? Irú kí ni o ṣe sí wa yìí, tí o kó wa kúrò ní Ijipti?

12 Ṣebí a sọ fún ọ ní Ijipti pé kí o fi wá sílẹ̀ kí á máa sin àwọn ará Ijipti tí à ń sìn, nítorí pé kì bá sàn kí á máa sin àwọn ará Ijipti ju kí á wá kú sinu aṣálẹ̀ lọ.”

13 Mose bá dá àwọn eniyan náà lóhùn, ó ní, “Ẹ má bẹ̀rù, ẹ dúró gbọningbọnin, kí ẹ wá máa wo ohun tí OLUWA yóo ṣe. Ẹ óo rí i bí yóo ṣe gbà yín là lónìí; nítorí pé àwọn ará Ijipti tí ẹ̀ ń wò yìí, ẹ kò tún ní rí wọn mọ́ laelae.

14 OLUWA yóo jà fún yín, ẹ̀yin ẹ ṣá dúró jẹ́.”

15 OLUWA wí fún Mose pé, “Kí ló dé tí o fi ń ké pè mí, sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé kí wọ́n tẹ̀síwájú.

16 Gbé ọ̀pá rẹ sókè kí o na ọwọ́ sórí Òkun Pupa, kí ó sì pín in sí meji, kí àwọn eniyan Israẹli lè kọjá láàrin rẹ̀ lórí ìyàngbẹ ilẹ̀.

17 N óo mú kí ọkàn àwọn ará Ijipti le, kí wọ́n sì tẹ̀lé àwọn ọmọ Israẹli wọ inú Òkun Pupa, n óo sì gba ògo lórí Farao ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀, àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, ati àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀.

18 Àwọn ará Ijipti yóo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA, nígbà tí mo bá gba ògo lórí Farao ati kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, ati àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀.”

19 Angẹli Ọlọrun tí ó ti wà níwájú àwọn eniyan Israẹli bá bọ́ sẹ́yìn wọn, ọ̀wọ̀n ìkùukùu tí ó wà níwájú wọn náà bá pada sí ẹ̀yìn wọn.

20 Ọ̀wọ̀n ìkùukùu náà sì wà láàrin àwọn ọmọ ogun Ijipti ati àwọn ọmọ ogun Israẹli, ìkùukùu náà ṣókùnkùn dudu títí tí gbogbo òru ọjọ́ náà fi kọjá, wọn kò sì súnmọ́ ara wọn.

21 Mose na ọwọ́ rẹ̀ sórí Òkun Pupa; OLUWA bá mú kí afẹ́fẹ́ líle kan fẹ́ wá láti ìhà ìlà oòrùn ní gbogbo òru náà, afẹ́fẹ́ náà bi omi òkun sẹ́yìn, ó sì mú kí ààrin òkun náà di ìyàngbẹ ilẹ̀, omi rẹ̀ sì pín sí ọ̀nà meji.

22 Àwọn ọmọ Israẹli bọ́ sí ààrin òkun náà lórí ìyàngbẹ ilẹ̀, omi òkun wá dàbí ògiri ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún ati ní ẹ̀gbẹ́ òsì wọn.

23 Àwọn ará Ijipti lé wọn wọ inú òkun, tàwọn ti gbogbo ẹṣin Farao ati gbogbo kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ ati gbogbo ẹlẹ́ṣin rẹ̀.

24 Nígbà tí ó di òwúrọ̀ kutukutu, OLUWA bojú wo ogun Ijipti láti òkè wá, ninu ọ̀wọ̀n iná, ati ọ̀wọ̀n ìkùukùu, ó sì dẹ́rùbà wọ́n.

25 Ó mú kí ẹsẹ̀ kẹ̀kẹ́ ogun wọ́n há, tí ó fi jẹ́ pé àwọn kẹ̀kẹ́ náà wúwo rinrin. Àwọn ọmọ ogun Ijipti bá wí láàrin ara wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí á sá fún àwọn ọmọ Israẹli, nítorí pé, OLUWA Ọlọrun ń bá wa jà nítorí wọn.”

26 Ọlọrun bá sọ fún Mose pé, “Na ọwọ́ rẹ sórí òkun pupa kí omi lè bo àwọn ará Ijipti ati kẹ̀kẹ́ ogun wọn, ati àwọn ẹlẹ́ṣin wọn mọ́lẹ̀.”

27 Mose bá na ọwọ́ sórí òkun, òkun bá bẹ̀rẹ̀ sí ṣàn gẹ́gẹ́ bí ó ti ń ṣàn tẹ́lẹ̀ nígbà tí ilẹ̀ ọjọ́ keji yóo fi mọ́; àwọn ará Ijipti gbìyànjú láti jáde, ṣugbọn OLUWA pa wọ́n run sinu òkun náà.

28 Omi òkun pada sí ipò rẹ̀, ó sì bo gbogbo kẹ̀kẹ́ ogun, ati àwọn ẹlẹ́ṣin, ati àwọn ọmọ ogun Farao tí wọ́n lépa àwọn ọmọ Israẹli wọ inú Òkun Pupa, ẹyọ kan kò sì yè ninu wọn.

29 Ṣugbọn àwọn ọmọ Israẹli rìn kọjá lórí ìyàngbẹ ilẹ̀ ninu Òkun Pupa, omi rẹ̀ sì dàbí ògiri ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún ati ní ẹ̀gbẹ́ òsì wọn.

30 Bẹ́ẹ̀ ni OLUWA ṣe gba Israẹli lọ́wọ́ àwọn ará Ijipti ní ọjọ́ náà, àwọn ọmọ Israẹli sì rí i bí àwọn ará Ijipti ti kú sí etí bèbè òkun.

31 Àwọn ọmọ Israẹli rí ohun ńlá tí OLUWA ṣe sí àwọn ará Ijipti, wọ́n bẹ̀rù OLUWA, wọ́n sì gba OLUWA gbọ́, ati Mose, iranṣẹ rẹ̀.

Categories
ẸKISODU

ẸKISODU 15

Orin Mose

1 Lẹ́yìn náà, Mose ati àwọn ọmọ Israẹli kọ orin yìí sí OLUWA, wọ́n ní:

“N óo kọrin sí OLUWA,

nítorí pé, ó ti ja àjàṣẹ́gun tí ó lógo.

Àtẹṣin, àtẹni tí ń gùn ún ni ó dà sinu Òkun Pupa.

2 OLUWA ni agbára ati orin mi,

ó ti gbà mí là, òun ni Ọlọrun mi,

n óo máa yìn ín.

Òun ni Ọlọrun àwọn baba ńlá mi;

n óo máa gbé e ga.

3 Jagunjagun ni OLUWA, OLUWA sì ni orúkọ rẹ̀.

4 Ó da kẹ̀kẹ́ ogun Farao ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sinu òkun,

ó sì ri àwọn akọni ọmọ ogun rẹ̀ sinu Òkun Pupa.

5 Ìkún omi bò wọ́n mọ́lẹ̀,

wọ́n rilẹ̀ sinu ibú omi bí òkúta.

6 Agbára ọwọ́ ọ̀tún rẹ pọ̀ jọjọ, OLUWA;

OLUWA, ọwọ́ ọ̀tún rẹ ni ó fọ́ àwọn ọ̀tá túútúú.

7 Ninu títóbi ọláńlá rẹ, o dojú àwọn ọ̀tá rẹ bolẹ̀,

o fa ibinu yọ, ó sì jó wọn bí àgékù koríko.

8 Èémí ihò imú rẹ mú kí omi gbájọ,

ìkún omi dúró lóòró bí òkítì,

ibú omi sì dì ní ìsàlẹ̀ òkun.

9 Ọ̀tá wí pé,

‘N óo lé wọn, ọwọ́ mi yóo sì tẹ̀ wọ́n;

n óo pín ìkógun,

n óo sì tẹ́ ìfẹ́ ọkàn mi lọ́rùn lára wọn.

N óo fa idà mi yọ,

ọwọ́ mi ni n óo sì fi pa wọ́n run.’

10 Ṣugbọn o fẹ́ afẹ́fẹ́ lù wọ́n,

òkun sì bò wọ́n mọ́lẹ̀,

wọ́n rì bí òjé ninu ibú ńlá.

11 “Ta ló dàbí rẹ OLUWA ninu àwọn oriṣa?

Ta ló dàbí rẹ, ológo mímọ̀ jùlọ?

Ẹlẹ́rù níyìn tíí ṣe ohun ìyanu.

12 O na ọwọ́ ọ̀tún rẹ,

ilẹ̀ sì yanu, ó gbé wọn mì.

13 O ti fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀

ṣe amọ̀nà àwọn eniyan rẹ tí o rà pada,

o ti fi agbára rẹ tọ́ wọn lọ sí ibùgbé mímọ́ rẹ.

14 Àwọn eniyan ti gbọ́, wọ́n wárìrì,

jìnnìjìnnì sì dà bo gbogbo àwọn olùgbé ilẹ̀ Filistini.

15 Ẹnu ya àwọn ìjòyè Edomu,

ojora sì mú gbogbo àwọn olórí ní ilẹ̀ Moabu,

gbogbo àwọn tí ń gbé Kenaani sì ti kú sára.

16 Ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ ati jìnnìjìnnì ti dà bò wọ́n,

nítorí títóbi agbára rẹ, OLUWA,

wọ́n dúró bí òkúta,

títí tí àwọn eniyan rẹ fi kọjá lọ,

àní àwọn tí o ti rà pada.

17 O óo kó àwọn eniyan rẹ wọlé,

o óo sì fi ìdí wọn múlẹ̀ lórí òkè mímọ́ rẹ,

níbi tí ìwọ OLUWA ti pèsè fún ibùgbé rẹ,

ibi mímọ́ rẹ tí ìwọ OLUWA ti fi ọwọ́ ara rẹ pèsè sílẹ̀.

18 OLUWA yóo jọba títí lae ati laelae.”

Orin Miriamu

19 Nígbà tí àwọn ẹṣin Farao, ati àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, ati àwọn ẹlẹ́ṣin wọ inú òkun, OLUWA mú kí omi òkun pada bò wọ́n mọ́lẹ̀, ṣugbọn àwọn eniyan Israẹli rìn lórí ìyàngbẹ ilẹ̀ láàrin òkun.

20 Nígbà náà ni Miriamu, wolii obinrin, tíí ṣe arabinrin Aaroni, gbé ìlù timbireli lọ́wọ́, gbogbo àwọn obinrin sì tẹ̀lé e, wọ́n ń lu timbireli, wọ́n sì ń jó.

21 Miriamu bá dá orin fún wọn pé,

“Ẹ kọrin sí OLUWA,

nítorí tí ó ti ja àjàṣẹ́gun tí ó lógo,

ó ti da ati ẹṣin ati àwọn ẹlẹ́ṣin sinu Òkun Pupa.”

Omi Kíkorò

22 Mose bá bẹ̀rẹ̀ sí kó àwọn ọmọ Israẹli tẹ̀síwájú láti ibi Òkun Pupa, wọ́n ń lọ sí aṣálẹ̀ Ṣuri, ọjọ́ mẹta ni wọ́n fi rìn ninu aṣálẹ̀ láìrí omi.

23 Nígbà tí wọ́n dé Mara, wọn kò lè mu omi tí wọ́n rí níbẹ̀, nítorí pé ó korò. Nítorí náà, wọ́n sọ orúkọ ibẹ̀ ní Mara, ìtumọ̀ èyí tíí ṣe ìkorò.

24 Ni àwọn eniyan náà bá bẹ̀rẹ̀ sí kùn sí Mose, wọ́n ní, “Kí ni a óo mu?”

25 Mose bá kígbe sí OLUWA, OLUWA fi igi kan hàn án. Mose ju igi náà sinu omi, omi náà sì di dídùn.

Ibẹ̀ ni OLUWA ti fún wọn ní ìlànà ati òfin, ó sì dán wọn wò,

26 ó ní, “Bí ẹ bá farabalẹ̀ gbọ́ ohùn èmi OLUWA Ọlọrun yín, tí ẹ sì ṣe ohun tí ó tọ́ lójú mi, tí ẹ pa gbogbo òfin mi mọ́, tí ẹ sì tẹ̀lé gbogbo ìlànà mi, èmi OLUWA kò ní fi èyíkéyìí ninu àwọn àrùn tí mo fi ṣe àwọn ará Ijipti ṣe yín, nítorí pé, èmi ni OLUWA, olùwòsàn yín.”

27 Lẹ́yìn náà ni wọ́n dé Elimu, níbi tí orísun omi mejila ati aadọrin igi ọ̀pẹ wà, wọ́n sì pàgọ́ sẹ́bàá àwọn orísun omi náà.

Categories
ẸKISODU

ẸKISODU 16

Mana ati Àparò

1 Nígbà tí ó yá, gbogbo ìjọ eniyan Israẹli jáde kúrò ní Elimu, wọ́n lọ sí aṣálẹ̀ Sini tí ó wà ní ààrin Elimu ati Sinai, ní ọjọ́ kẹẹdogun oṣù keji tí wọ́n jáde kúrò ní Ijipti ni wọ́n dé aṣálẹ̀ náà.

2 Gbogbo ìjọ eniyan Israẹli bá bẹ̀rẹ̀ sí kùn sí Mose ati Aaroni ninu aṣálẹ̀,

3 wọ́n ń wí pé, “Ìbá sàn kí OLUWA pa wá sí ilẹ̀ Ijipti, níbi tí olukuluku wa ti jókòó ti ìsaasùn ọbẹ̀ ẹran, tí a sì ń jẹ oúnjẹ àjẹyó, ju bí ẹ ti kó wa wá sí ààrin aṣálẹ̀ yìí lọ, láti fi ebi pa gbogbo wa kú.”

4 OLUWA bá sọ fún Mose pé, “Wò ó, n óo rọ̀jò oúnjẹ fún yín láti ọ̀run. Kí àwọn eniyan máa jáde lọ ní ojoojumọ, kí wọ́n sì máa kó ìwọ̀nba ohun tí wọn yóo jẹ ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan. N óo fi èyí dán wọn wò, kí n fi mọ̀ bóyá wọn yóo máa tẹ̀lé òfin mi tabi wọn kò ní tẹ̀lé e.

5 Nígbà tí ó bá di ọjọ́ kẹfa, kí wọ́n kó oúnjẹ wálé kí ó tó ìlọ́po meji èyí tí wọn ń kó ní ojoojumọ.”

6 Mose ati Aaroni bá sọ fún gbogbo àwọn eniyan Israẹli pé, “Ní ìrọ̀lẹ́ òní ni ẹ óo mọ̀ pé OLUWA ló mú yín jáde láti ilẹ̀ Ijipti.

7 Nígbà tí ó bá di òwúrọ̀ ọ̀la, ẹ óo rí ògo OLUWA, nítorí ó ti gbọ́ kíkùn tí ẹ̀ ń kùn sí i. Kí ni àwa yìí jẹ́, tí ẹ óo fi máa kùn sí wa?”

8 Mose ní, “OLUWA tìkararẹ̀ ni yóo fún yín ní ẹran ní ìrọ̀lẹ́, ati burẹdi ní òwúrọ̀. Ẹ óo jẹ àjẹyó, nítorí pé ó ti gbọ́ gbogbo kíkùn tí ẹ̀ ń kùn sí i; nítorí pé kí ni àwa yìí jẹ́? Gbogbo kíkùn tí ẹ̀ ń kùn, àwa kọ́ ni ẹ̀ ń kùn sí, OLUWA gan-an ni ẹ̀ ń kùn sí.”

9 Mose sọ fún Aaroni pé, “Sọ fún gbogbo ìjọ eniyan Israẹli pé, kí wọ́n súnmọ́ tòsí ọ̀dọ̀ OLUWA, nítorí pé ó ti gbọ́ gbogbo kíkùn wọn.”

10 Bí Aaroni ti ń bá gbogbo ìjọ eniyan Israẹli sọ̀rọ̀, wọ́n wo apá aṣálẹ̀, wọ́n sì rí i pé ògo OLUWA hàn ninu ìkùukùu.

11 OLUWA bá wí fún Mose pé,

12 “Mo ti gbọ́ kíkùn tí àwọn ọmọ Israẹli ń kùn, wí fún wọn pé, ‘Ní ìrọ̀lẹ́, ẹ óo máa jẹ ẹran, ní òwúrọ̀, ẹ óo máa jẹ burẹdi ní àjẹyó. Nígbà náà ni ẹ óo tó mọ̀ pé èmi ni OLUWA Ọlọrun yín.’ ”

13 Nígbà tí ó di ìrọ̀lẹ́, àwọn ẹyẹ àparò fò dé, wọ́n sì bo gbogbo àgọ́ náà; nígbà tí ilẹ̀ ọjọ́ keji mọ́, ìrì sẹ̀ bo gbogbo àgọ́ náà.

14 Nígbà tí ìrì náà kásẹ̀ nílẹ̀, wọ́n rí i tí kinní funfun kan tí ó dàbí ìrì dídì bo ilẹ̀ ní gbogbo aṣálẹ̀ náà.

15 Nígbà tí àwọn eniyan Israẹli rí i, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bi ara wọn léèrè pé, “Kí nìyí?” Nítorí pé, wọn kò mọ ohun tíí ṣe.

Mose bá dá wọn lóhùn pé, “Oúnjẹ tí OLUWA fún yín láti jẹ ni.

16 Àṣẹ tí OLUWA pa ni pé, ‘Kí olukuluku yín kó ìwọ̀nba tí ó lè jẹ tán, kí ẹ kó ìwọ̀n Omeri kan fún ẹnìkọ̀ọ̀kan ninu àgọ́ yín.’ ”

17 Àwọn eniyan Israẹli sì ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn mìíràn kó ju ohun tí ó yẹ kí wọ́n kó, àwọn mìíràn kò sì kó tó.

18 Ṣugbọn nígbà tí wọn fi ìwọ̀n Omeri wọ̀n ọ́n, àwọn tí wọ́n kó pupọ jù rí i pé, ohun tí wọ́n kó, kò lé nǹkankan; àwọn tí wọn kò sì kó pupọ rí i pé ohun tí wọ́n kó tó wọn; olukuluku kó ìwọ̀n tí ó lè jẹ.

19 Mose wí fún wọn pé, “Kí ẹnikẹ́ni má ṣe ṣẹ́ ohunkohun kù di òwúrọ̀ ọjọ́ keji.”

20 Ṣugbọn wọn kò gbọ́rọ̀ sí Mose lẹ́nu; àwọn mìíràn ṣẹ́ ẹ kù di òwúrọ̀ ọjọ́ keji, nígbà tí ilẹ̀ ọjọ́ keji mọ́, ohun tí wọ́n ṣẹ́kù ti bẹ̀rẹ̀ sí yọ ìdin, ó sì ń rùn, Mose bá bínú sí wọn.

21 Ní àràárọ̀ ni olukuluku máa ń kó ohun tí ó bá lè jẹ tán, nígbà tí oòrùn bá gòkè, gbogbo èyí tí ó bá wà nílẹ̀ yóo sì yọ́ dànù.

22 Nígbà tí ó di ọjọ́ kẹfa, wọ́n kó ìlọ́po meji, olukuluku kó ìwọ̀n Omeri meji meji. Nígbà tí àwọn àgbààgbà Israẹli lọ sọ fún Mose,

23 ó wí fún wọn pé, “Ohun tí OLUWA wí nìyí, ‘Ọ̀la ni ọjọ́ ìsinmi tí ó ní ọ̀wọ̀, ọjọ́ ìsinmi mímọ́ fún OLUWA. Ẹ dín ohun tí ẹ bá fẹ́ dín, kí ẹ sì se ohun tí ẹ bá fẹ́ sè, ohun tí ó bá ṣẹ́kù, ẹ fi pamọ́ títí di òwúrọ̀ ọ̀la.’ ”

24 Wọ́n bá fi ìyókù pamọ́ títí di òwúrọ̀ gẹ́gẹ́ bí Mose ti sọ fún wọn; kò sì rùn, bẹ́ẹ̀ ni kò yọ ìdin.

25 Mose wí fún wọn pé, “Ẹ jẹ èyí lónìí, nítorí pé òní ni ọjọ́ ìsinmi OLUWA, ẹ kò ní rí kó rárá ní òní.

26 Ọjọ́ mẹfa ni ẹ óo fi máa rí oúnjẹ kó, ṣugbọn ní ọjọ́ keje tíí ṣe ọjọ́ ìsinmi, kò ní sí níbẹ̀ rárá.”

27 Ní ọjọ́ keje, àwọn mìíràn ninu àwọn eniyan náà jáde láti lọ kó oúnjẹ, ṣugbọn wọn kò rí ohunkohun.

28 OLUWA bá wí fún Mose pé, “Yóo ti pẹ́ tó, tí ẹ óo fi kọ̀ láti pa àṣẹ ati òfin mi mọ́.

29 Ẹ wò ó! OLUWA ti fún yín ní ọjọ́ ìsinmi, nítorí náà ni ó fi jẹ́ pé, ní ọjọ́ kẹfa ó fún yín ní oúnjẹ fún ọjọ́ meji, kí olukuluku lè dúró sí ààyè rẹ̀, kí ẹnikẹ́ni má ṣe jáde ní ilé rẹ̀ ní ọjọ́ keje.”

30 Àwọn eniyan náà bá sinmi ní ọjọ́ keje.

31 Àwọn eniyan Israẹli pe orúkọ oúnjẹ náà ní mana, ó rí rínbíntín-rínbíntín, ó dàbí èso igi korianda, ó funfun, ó sì dùn lẹ́nu bíi burẹdi fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tí wọ́n fi oyin ṣe.

32 Mose wí fún wọn pé, “Àṣẹ tí OLUWA pa nìyí: ‘Ẹ fi ìwọ̀n omeri kan pamọ́ láti ìrandíran yín, kí àwọn ọmọ yín lè rí irú oúnjẹ tí mo fi bọ́ yín ninu aṣálẹ̀ nígbà tí mo ko yín jáde láti ilẹ̀ Ijipti wá.’ ”

33 Mose bá sọ fún Aaroni pé, “Mú ìkòkò kan kí o fi ìwọ̀n omeri mana kan sinu rẹ̀, kí o gbé e kalẹ̀ níwájú OLUWA, kí ẹ pa á mọ́ láti ìrandíran yín.”

34 Aaroni bá gbé e kalẹ̀ níwájú àpótí ẹ̀rí, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí OLUWA ti pa fún Mose.

35 Àwọn eniyan Israẹli jẹ mana náà fún ogoji ọdún, títí wọ́n fi dé ilẹ̀ tí wọ́n lè máa gbé, òun ni wọ́n jẹ títí tí wọ́n fi dé etí ilẹ̀ Kenaani.

36 Ìwọ̀n omeri kan jẹ́ ìdámẹ́wàá ìwọ̀n efa kan.

Categories
ẸKISODU

ẸKISODU 17

Omi Jáde láti Inú Àpáta

1 Gbogbo ìjọ eniyan Israẹli gbéra láti aṣálẹ̀ Sini, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí lọ láti ibùsọ̀ kan dé ekeji, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí OLUWA pa fún wọn. Wọ́n pàgọ́ sí Refidimu, ṣugbọn kò sí omi fún wọn láti mu.

2 Wọ́n bá ka ẹ̀sùn sí Mose lẹ́sẹ̀, wọ́n ní, “Fún wa ní omi tí a óo mu.”

Mose dá wọn lóhùn pé, “Kí ló dé tí ẹ fi ka ẹ̀sùn sí mi lẹ́sẹ̀? Kí ló dé tí ẹ sì fi ń dán OLUWA wò?”

3 Ṣugbọn òùngbẹ ń gbẹ àwọn eniyan náà, wọ́n fẹ́ mu omi, wọ́n bá ń kùn sí Mose, wọ́n wí pé, “Kí ló dé tí o fi kó wa jáde láti ilẹ̀ Ijipti, láti fi òùngbẹ pa àwa ati àwọn ọmọ wa, ati àwọn ẹran ọ̀sìn wa?”

4 Mose bá tún kígbe pe OLUWA, ó ní, “Kí ni n óo ṣe sí àwọn eniyan wọnyi, wọ́n ti múra láti sọ mí lókùúta.”

5 OLUWA bá sọ fún Mose pé, “Mú ninu àwọn àgbààgbà ilẹ̀ Israẹli lọ́wọ́, kí ẹ jọ la ààrin àwọn eniyan náà kọjá, kí o sì mú ọ̀pá tí o fi lu odò Naili lọ́wọ́, bí o bá ti ń lọ.

6 N óo dúró níwájú rẹ lórí àpáta ní òkè Horebu. Nígbà tí o bá fi ọ̀pá lu àpáta náà, omi yóo ti inú rẹ̀ jáde, àwọn eniyan náà yóo sì mu ún.” Mose bá ṣe bẹ́ẹ̀ níwájú gbogbo àwọn àgbààgbà Israẹli.

7 Ó sì pe orúkọ ibẹ̀ ní Masa ati Meriba, nítorí ìwà ìka-ẹ̀sùn-síni-lẹ́sẹ̀ tí àwọn ọmọ Israẹli hù, ati nítorí dídán tí wọn dán OLUWA wò, wọ́n ní, “Ṣé OLUWA tún wà láàrin wa ni tabi kò sí mọ́?”

Wọ́n Bá Àwọn Ará Amaleki Jagun

8 Lẹ́yìn èyí ni àwọn ará Amaleki wá, wọ́n sì bá àwọn ọmọ Israẹli jagun ní Refidimu.

9 Mose bá wí fún Joṣua pé, “Yan àwọn akọni ọkunrin láàrin yín kí o sì jáde lọ láti bá àwọn ará Amaleki jagun lọ́la, n óo dúró ní orí òkè pẹlu ọ̀pá Ọlọrun ní ọwọ́ mi.”

10 Joṣua ṣe bí Mose ti pàṣẹ fún un, ó bá àwọn ará Amaleki jagun. Mose ati Aaroni ati Huri bá gun orí òkè lọ.

11 Nígbà tí Mose bá gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè, àwọn ọmọ Israẹli a máa borí àwọn ará Amaleki, nígbà tí ó bá sì rẹ ọwọ́ sílẹ̀, àwọn ará Amaleki a máa borí àwọn ọmọ Israẹli.

12 Nígbà tí ó yá, apá bẹ̀rẹ̀ sí ro Mose, wọ́n gbé òkúta kan fún un láti fi jókòó, ó sì jókòó lórí rẹ̀. Aaroni ati Huri bá a gbé apá rẹ̀ sókè, ẹnìkan gbé apá ọ̀tún, ẹnìkejì sì gbé apá òsì. Apá rẹ̀ wà lókè títí tí oòrùn fi ń lọ wọ̀.

13 Joṣua bá fi idà pa Amaleki ati àwọn eniyan rẹ̀ ní ìpakúpa.

14 OLUWA bá sọ fún Mose pé, “Kọ ìṣẹ̀lẹ̀ yìí sinu ìwé kan fún ìrántí, sì kà á sí etígbọ̀ọ́ Joṣua, pé n óo pa Amaleki rẹ́ patapata, a kò sì ní ranti rẹ̀ mọ́ láyé.”

15 Mose bá tẹ́ pẹpẹ kan, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní “OLUWA ni àsíá mi.”

16 Ó ní, “Gbé àsíá OLUWA sókè!OLUWA yóo máa bá ìrandíran àwọn ará Amaleki jà títí lae.”

Categories
ẸKISODU

ẸKISODU 18

Jẹtiro Lọ Bẹ Mose Wò

1 Jẹtiro, alufaa àwọn ará Midiani, baba iyawo Mose, gbọ́ gbogbo ohun tí Ọlọrun ti ṣe fún Mose ati fún Israẹli, àwọn eniyan rẹ̀, ati bí ó ti mú wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti.

2 Jẹtiro, baba iyawo Mose mú Sipora aya Mose, lẹ́yìn tí Mose ti dá a pada sọ́dọ̀ baba rẹ̀ tẹ́lẹ̀,

3 ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin mejeeji. Orúkọ ọmọ rẹ̀ kinni ni Geriṣomu, (ìtumọ̀ rẹ̀ ni pé, “Mo ti jẹ́ àtìpó ní ilẹ̀ àjèjì.”)

4 Orúkọ ọmọ keji ni Elieseri, (ìtumọ̀ rẹ̀ ni pé, “Ọlọrun baba mi ni olùrànlọ́wọ́ mi, òun ni ó sì gbà mí kúrò lọ́wọ́ idà Farao.”)

5 Jẹtiro, baba iyawo Mose, mú iyawo Mose, ati àwọn ọmọ rẹ̀ mejeeji tọ̀ ọ́ wá ní aṣálẹ̀, níbi tí wọ́n pàgọ́ sí níbi òkè Ọlọrun.

6 Nígbà tí wọ́n sọ fún Mose pé Jẹtiro, baba iyawo rẹ̀, ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀ pẹlu iyawo rẹ̀ ati àwọn ọmọ rẹ̀ mejeeji,

7 Mose lọ pàdé wọn, ó wólẹ̀ níwájú Jẹtiro, ó fi ẹnu kò ó lẹ́nu, wọ́n bèèrè alaafia ara wọn, wọ́n sì wọ inú àgọ́ lọ.

8 Gbogbo ohun tí Ọlọrun ṣe sí Farao ati sí àwọn ará Ijipti nítorí àwọn ọmọ Israẹli ni Mose ròyìn fún baba iyawo rẹ̀. Ó sọ gbogbo ìṣòro tí wọ́n rí lójú ọ̀nà, ati bí OLUWA ti kó wọn yọ.

9 Jẹtiro sì bá wọn yọ̀ nítorí gbogbo oore tí OLUWA ti ṣe fún àwọn ọmọ Israẹli, nítorí gbígbà tí ó gbà wọ́n kalẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Ijipti.

10 Jẹtiro dáhùn, ó ní, “Ẹni ìyìn ni OLUWA, tí ó gbà yín kalẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Ijipti ati lọ́wọ́ Farao.

11 Mo mọ̀ nisinsinyii pé OLUWA ju gbogbo àwọn oriṣa lọ, nítorí pé ó ti gba àwọn eniyan náà lọ́wọ́ àwọn ará Ijipti, nígbà tí àwọn ará Ijipti ń lò wọ́n ní ìlò àbùkù ati ẹ̀gàn.”

12 Jẹtiro bá rú ẹbọ sísun sí Ọlọrun. Aaroni ati àwọn àgbààgbà Israẹli sì wá sọ́dọ̀ Jẹtiro, láti bá a jẹun níwájú Ọlọrun.

Yíyan Àwọn Onídàájọ́

(Diut 1:9-18)

13 Ní ọjọ́ keji, Mose jókòó, ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìdájọ́ fún àwọn ọmọ Israẹli, àwọn eniyan wà lọ́dọ̀ rẹ̀ láti òwúrọ̀ títí di àṣáálẹ́.

14 Nígbà tí baba iyawo Mose rí gbogbo ohun tí Mose ń ṣe fún àwọn eniyan, ó pè é, ó ní, “Kí ni gbogbo ohun tí ò ń ṣe fún àwọn eniyan wọnyi? Kí ló dé tí o fi wà lórí àga ìdájọ́ láti òwúrọ̀ títí di àṣáálẹ́, tí àwọn eniyan ń kó ẹjọ́ wá bá ìwọ nìkan?”

15 Mose dáhùn pé, “Ọ̀dọ̀ mi ni àwọn eniyan náà ti máa ń bèèrè ohun tí Ọlọrun fẹ́ kí wọ́n ṣe.

16 Nígbà tí èdè-àìyedè bá wà láàrin àwọn aládùúgbò meji, èmi ni mo máa ń parí rẹ̀ fún wọn. Èmi náà ni mo sì máa ń sọ òfin Ọlọrun, ati àwọn ìpinnu rẹ̀ fún wọn.”

17 Baba iyawo rẹ̀ bá bá a wí pé, “Ohun tí ò ń ṣe yìí kò dára.

18 Àtìwọ àtàwọn eniyan tí wọ́n wà pẹlu rẹ, ẹ óo pa ara yín; ohun tí ò ń ṣe yìí ti pọ̀ jù fún ọ, o kò lè dá a ṣe.

19 Gbọ́ ohun tí n óo sọ fún ọ yìí, ìmọ̀ràn ni mo fẹ́ gbà ọ́, Ọlọrun yóo sì wà pẹlu rẹ. Ó dára kí o máa ṣe aṣojú àwọn eniyan náà níwájú Ọlọrun, kí o sì máa bá wọn kó ẹ̀dùn ọkàn wọn tọ Ọlọrun lọ;

20 ó sì dára bákan náà pẹlu kí o máa kọ́ wọn ní òfin ati ìlànà, kí o sì máa fi ọ̀nà tí wọn yóo tọ̀ hàn wọ́n, ati ohun tí wọ́n gbọdọ̀ máa ṣe.

21 Ohun tí ó yẹ kí o ṣe nìyí, yan àwọn ọkunrin tí wọ́n lè jẹ́ alákòóso, àwọn tí wọ́n bẹ̀rù Ọlọrun, tí wọ́n ṣe é gbẹ́kẹ̀lé, tí wọ́n sì kórìíra àbẹ̀tẹ́lẹ̀; fi wọ́n ṣe alákòóso àwọn eniyan wọnyi, fi àwọn kan ṣe alákòóso lórí ẹgbẹẹgbẹrun eniyan, àwọn kan lórí ọgọọgọrun-un eniyan, àwọn kan lórí araadọta, ati àwọn mìíràn lórí eniyan mẹ́wàá mẹ́wàá.

22 Jẹ́ kí wọn máa ṣe onídàájọ́ fún àwọn eniyan náà nígbà gbogbo; àwọn ọ̀rọ̀ tí ó bá jẹ́ pataki pataki nìkan ni wọn yóo máa kó wá sí ọ̀dọ̀ rẹ, kí wọ́n máa parí àwọn ẹjọ́ kéékèèké láàrin ara wọn. Èyí yóo mú kí ó rọ̀ ọ́ lọ́rùn, wọn yóo sì máa bá ọ gbé ninu ẹrù náà.

23 Bí Ọlọrun bá gbà fún ọ láti ṣe bẹ́ẹ̀, tí o sì ṣe é, ẹ̀mí rẹ yóo gùn, gbogbo àwọn eniyan wọnyi náà yóo sì pada sí ilé wọn ní alaafia.”

24 Mose gba ọ̀rọ̀ tí baba iyawo rẹ̀ sọ, ó sì ṣe gẹ́gẹ́ bí ìmọ̀ràn tí ó fún un.

25 Mose yan àwọn ọkunrin tí wọ́n lè ṣe alákòóso ninu àwọn eniyan Israẹli, ó fi wọ́n ṣe olórí àwọn eniyan náà, àwọn kan jẹ́ alákòóso fún ẹgbẹẹgbẹrun eniyan, àwọn mìíràn, fún ọgọọgọrun-un eniyan, àwọn mìíràn, fún araadọta, àwọn mìíràn fún eniyan mẹ́wàá mẹ́wàá.

26 Wọ́n ń ṣe ìdájọ́ àwọn eniyan náà nígbà gbogbo; àwọn ọ̀rọ̀ tí ó bá fẹ́ díjú nìkan ni wọ́n ń kó tọ Mose lọ, wọ́n ń yanjú àwọn ọ̀rọ̀ kéékèèké láàrin ara wọn.

27 Mose gbà fún baba iyawo rẹ̀ pé kí ó máa pada lọ sí ìlú rẹ̀, baba iyawo rẹ̀ gbéra, ó sì pada sí orílẹ̀-èdè rẹ̀.