Categories
JOBU

JOBU 17

1 “Ọkàn mi bàjẹ́, ọjọ́ ayé mi ti dópin,

ibojì sì ń dúró dè mí.

2 Dájúdájú àwọn ẹlẹ́yà yí mi káàkiri,

wọ́n ń fi mí ṣe yẹ̀yẹ́ lojukooju.

3 Fi nǹkan ẹ̀jẹ́ kan lélẹ̀ fún mi lọ́dọ̀ rẹ;

ta ló wà níbẹ̀ tí yóo ṣe onídùúró fún mi?

4 Níwọ̀n ìgbà tí o ti mú ọkàn wọn yigbì sí ìmọ̀,

nítorí náà, o kò ní jẹ́ kí wọ́n borí.

5 Bí ẹnìkan bá hùwà ọ̀dàlẹ̀, tí ó ṣòfófó àwọn ọ̀rẹ́,

kí ó lè pín ninu ohun ìní wọn,

àwọn ọmọ olúwarẹ̀ yóo jìyà.

6 O ti sọ mí di ẹni àmúpòwe láàrin àwọn eniyan,

mo di ẹni tí à ń tutọ́ sí lára.

7 Ìbànújẹ́ sọ ojú mi di bàìbàì,

gbogbo ẹ̀yà ara mi dàbí òjìji.

8 Èyí ya àwọn olódodo lẹ́nu,

aláìlẹ́bi sì dojú kọ ẹni tí kò mọ Ọlọrun.

9 Sibẹsibẹ olódodo kò fi ọ̀nà rẹ̀ sílẹ̀,

ẹni tí ọwọ́ rẹ̀ mọ́ sì ń lágbára sí i.

10 Ṣugbọn ní tiyín, bí ẹ tilẹ̀ ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ,

n kò ní ka ẹnikẹ́ni kún ọlọ́gbọ́n láàrin yín.

11 “Ọjọ́ ayé mi ti dópin, èrò ọkàn mi ti dàrú,

àwọn ohun tí ọkàn mi ń fẹ́ sì ti di asán.

12 Wọ́n sọ òru di ọ̀sán,

wọ́n ń sọ pé, ‘Ìmọ́lẹ̀ kò jìnnà sí òkùnkùn.’

13 Bí mo bá ní ìrètí pé ibojì yóo jẹ́ ilé mi,

tí mo tẹ́ ibùsùn mi sinu òkùnkùn,

14 bí mo bá pe isà òkú ní baba,

tí mo sì pe ìdin ní ìyá tabi arabinrin mi,

15 níbo ni ìrètí mi wá wà?

Ta ló lè rí ìrètí mi?

16 Ṣé yóo lọ sí ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ ni?

Ṣé àwa mejeeji ni yóo jọ wọ inú erùpẹ̀ lọ?”

Categories
JOBU

JOBU 18

1 Bilidadi ará Ṣuha bá tún dáhùn pé,

2 “Ìgbàwo ni o óo sinmi ẹjọ́ tí ò ń tò yìí?

Ohun tí a tí ń bá ọ sọ ni kí o gbé yẹ̀wò,

kí á lè sọ èyí tí a tún fẹ́ sọ.

3 Kí ló dé tí o fi kà wá sí ẹranko,

tí a di òmùgọ̀ lójú rẹ?

4 Ìwọ tí o faraya nítorí inú ń bí ọ,

ṣé kí á sá kúrò láyé nítorí rẹ ni,

tabi kí á ṣí àwọn àpáta nípò pada?

5 “Nítòótọ́, a ti pa fìtílà ẹni ibi,

ahọ́n iná rẹ̀ kò sì mọ́lẹ̀ mọ́.

6 Inú àgọ́ rẹ̀ ṣókùnkùn,

a sì ti pa àtùpà ìgbèrí rẹ̀.

7 Agbára rẹ̀ ti dín kù,

ète rẹ̀ sì gbé e ṣubú.

8 Ó ti ẹsẹ̀ ara rẹ̀ bọ àwọ̀n,

ó ń rìn lórí ọ̀fìn.

9 Tàkúté ti mú un ní gìgísẹ̀,

ó ti kó sinu pańpẹ́.

10 A dẹ okùn sílẹ̀ fún un,

a sì dẹ pańpẹ́ sí ojú ọ̀nà rẹ̀.

11 “Ìbẹ̀rù yí i ká,

wọ́n ń lé e kiri.

12 Ebi pa agbára mọ́ ọn ninu,

ìṣòro sì ti ṣetán láti gbé e ṣubú.

13 Àìsàn burúkú jẹ awọ ara rẹ̀,

àkọ́bí ikú jẹ ẹ́ tọwọ́ tẹsẹ̀.

14 A fipá wọ́ ọ kúrò ninu àgọ́ rẹ̀ tí ó gbẹ́kẹ̀lé,

a sì mú un lọ sọ́dọ̀ Ọba Ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀.

15 Àgọ́ rẹ̀ kún fún àwọn tí kì í ṣe tirẹ̀,

imí-ọjọ́ fọ́nká sí gbogbo ibùgbé rẹ̀.

16 Gbòǹgbò rẹ̀ gbẹ nísàlẹ̀,

ẹ̀ka rẹ̀ sì gbẹ lókè.

17 Ó di ẹni ìgbàgbé lórílẹ̀ ayé,

bẹ́ẹ̀ ni a kò gbórúkọ rẹ̀ mọ́ ní ìgboro.

18 Wọ́n tì í láti inú ìmọ́lẹ̀ sinu òkùnkùn,

wọ́n lé e kúrò láyé.

19 Kò lọ́mọ, kò lọ́mọ ọmọ,

kò sì sí ẹni tí yóo rọ́pò rẹ̀ ní ibùgbé rẹ̀,

láàrin àwọn eniyan rẹ̀.

20 Ẹnu yóo ya àwọn ará ìwọ̀ oòrùn,

ìwárìrì yóo sì mú àwọn ará ìlà oòrùn,

nítorí ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ sí i.

21 Dájúdájú bẹ́ẹ̀ ni ibùgbé ẹni ibi yóo rí,

àní, ilé ẹni tí kò mọ Ọlọrun.”

Categories
JOBU

JOBU 19

1 Jobu bá dáhùn, ó ní,

2 “Ẹ óo ti ni mí lára pẹ́ tó,

tí ẹ óo máa fi ọ̀rọ̀ yín bà mí ninu jẹ́?

3 Ẹ kẹ́gàn mi ní àìníye ìgbà

ojú kò tilẹ̀ tì yín láti ṣẹ̀ mí?

4 Bí ó bá tilẹ̀ jẹ́ pé lótìítọ́ ni mo ṣẹ̀,

ṣebí ara mi ni àṣìṣe mi wà?

5 Bí ẹ bá rò pé ẹ sàn jù mí lọ,

tí ẹ sì rò pé ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ mi ni ìdààmú mi,

6 ẹ mọ̀ dájú pé Ọlọrun ni ó dá mi lẹ́bi,

tí ó sì fi àwọ̀n rẹ̀ yí mi ká.

7 Mò ń kérora pé wọ́n dá mi lóró,

ṣugbọn kò sí ẹni tí ó dá mi lóhùn;

mo pariwo, pariwo,

ṣugbọn kò sí ẹni tí ó dìde láti ṣe ẹ̀tọ́.

8 Ọlọrun ti dí ọ̀nà mọ́ mi, kí n má baà kọjá,

ó mú ọ̀nà mi ṣókùnkùn.

9 Ó bọ́ ògo mi kúrò,

ó sì gba adé orí mi.

10 Ó ba ayé mi jẹ́ ní gbogbo ọ̀nà,

ó sì ti parí fún mi,

ó fa ìrètí mi tu bí ẹni fa igi tu.

11 Ibinu rẹ̀ ń jó mi bí iná,

ó kà mí kún ọ̀tá rẹ̀.

12 Àwọn ọmọ ogun rẹ̀ kó ara wọn jọ,

wọ́n dó tì mí,

wọ́n sì pa àgọ́ tiwọn yí àgọ́ mi ká.

13 “Ó mú kí àwọn arakunrin mi jìnnà sí mi,

àwọn ojúlùmọ̀ mi sì di àjèjì sí mi.

14 Àwọn ìyekan mi ati àwọn ọ̀rẹ́ mi tímọ́tímọ́ ti já mi kulẹ̀.

15 Àwọn àlejò tí wọ́n wọ̀ sí ilé mi ti gbàgbé mi.

Àwọn iranṣẹbinrin mi kà mí kún àlejò,

wọ́n ń wò mí bí àjèjì.

16 Mo pe iranṣẹ mi, ṣugbọn kò dáhùn,

bíbẹ̀ ni mo níláti máa bẹ̀ ẹ́.

17 Mo di ẹni ìríra lọ́dọ̀ iyawo mi,

mo sì ń rùn sí àwọn ọmọ ìyá mi.

18 Àwọn ọmọde pàápàá ń fojú tẹmbẹlu mi;

bí mo bá dìde wọn á máa sọ̀rọ̀ sí mi.

19 Gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ mi tímọ́tímọ́ ti rí mi sá,

àwọn tí mo nífẹ̀ẹ́ ti kẹ̀yìn sí mi.

20 Mo rù kan egungun,

agbára káká ni mo fi sá àsálà.

21 Ẹ ṣàánú mi, ẹ ṣàánú mi, ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi,

nítorí ọwọ́ Ọlọrun ti bà mí!

22 Ọlọrun ń lépa mi,

ẹ̀yin náà sì tún ń lépa mi!

Kí ló dé tí ẹran ara mi kò to yín?

23 “À bá lè kọ ọ̀rọ̀ mi sílẹ̀!

Àní, kí á kọ ọ́ sinu ìwé!

24 Kí á fi kálàmú irin ati òjé

kọ ọ́ sórí àpáta, kí ó wà níbẹ̀ títí lae.

25 Ṣugbọn mo mọ̀ pé Olùdáǹdè mi ń bẹ láàyè,

ati pé, níkẹyìn, yóo dìde dúró lórí ilẹ̀ yóo sì jẹ́rìí mi,

26 lẹ́yìn tí awọ ara mi bá ti díbàjẹ́,

ṣugbọn ninu ara mi ni n óo rí Ọlọ́run.

27 Fúnra mi ni n óo rí i,

ojú ara mi ni n óo sì fi rí i,

kì í ṣe ti ẹlòmíràn.

“Ọkàn mi rẹ̀wẹ̀sì ninu mi!

28 Bí ẹ bá wí pé, ‘Báwo ni a óo ṣe lépa rẹ̀!’

Nítorí pé òun ló jẹ̀bi ọ̀rọ̀ yìí,

29 ṣugbọn, ẹ bẹ̀rù idà,

nítorí pé ìrúnú níí fa kí á fi idà pa eniyan,

kí ẹ lè mọ̀ dájú pé ìdájọ́ ń bẹ.”

Categories
JOBU

JOBU 20

1 Sofari, ará Naama bá dáhùn pé,

2 “Lọ́kàn mi, mo fẹ́ fèsì sí ọ̀rọ̀ rẹ,

ara sì ń wá mi, bí ẹni pé kí n dá ọ lóhùn.

3 Mo gbọ́ èébú tí o bú mi,

mo sì mọ irú èsì tí ó yẹ kí n fọ̀.

4 Ṣé o kò mọ̀ bẹ́ẹ̀ láti ìgbà àtijọ́,

láti ìgbà tí wọ́n ti dá eniyan sórí ilẹ̀ ayé,

5 pé bí inú eniyan burúkú bá ń dùn,

tí ẹni tí kò mọ Ọlọrun bá ń yọ̀, fún ìgbà díẹ̀ ni.

6 Bí ìgbéraga rẹ̀ tilẹ̀ ga, tí ó kan ọ̀run,

tí orí rẹ̀ kan sánmà,

7 yóo ṣòfò títí lae bí ìgbọ̀nsẹ̀ ara rẹ̀,

àwọn tí wọ́n mọ̀ ọ́n yóo bèèrè pé, ‘Níbo ló wà?’

8 Yóo parẹ́ bí àlá,

yóo sì di àwátì,

yóo pòórá bí ìran tí a rí lóru.

9 Ojú tí ó ti ń rí i tẹ́lẹ̀ kò ní rí i mọ́,

ààyè rẹ̀ yóo sì ṣófo.

10 Àwọn ọmọ rẹ̀ yóo máa wá ojurere àwọn aláìní,

wọn yóo sì san ohun tí baba wọn gbà lọ́wọ́ aláìní pada.

11 Bí ó tilẹ̀ dàbí ọ̀dọ́, tí ó lágbára,

sibẹ yóo lọ sí ibojì, yóo sì di erùpẹ̀.

12 Bí ọ̀rọ̀ ìkà tilẹ̀ dùn ní ẹnu rẹ̀,

tí ó sì fi pamọ́ sí abẹ́ ahọ́n rẹ̀,

13 bí ó tilẹ̀ lọ́ra láti sọ ọ́ jáde,

tí ó pa ẹnu mọ́,

14 sibẹsibẹ oúnjẹ rẹ̀ a máa dà á ninu rú,

ó sì ti dàbí oró ejò paramọ́lẹ̀ ninu rẹ̀.

15 Gbogbo owó tí ó kó jẹ ni ó tún ń pọ̀ jáde;

Ọlọrun ní ń pọ̀ wọ́n jáde ninu ikùn rẹ̀.

16 Yóo mu oró ejò,

ahọ́n paramọ́lẹ̀ yóo pa á.

17 Kò ní gbádùn oyin ati wàrà tí ń ṣàn bí odò.

18 Kò ní jẹ èrè wahala rẹ̀,

bẹ́ẹ̀ ni kò ní gbádùn èrè tí ó bá jẹ nídìí òwò rẹ̀.

19 Nítorí pé ó ti tẹ aláìní mọ́lẹ̀,

ó sì ti pa wọ́n tì sí apákan

ó sì fi ipá gba ilé tí kò kọ́.

20 Nítorí pé oníwọ̀ra ni,

tí ọkàn rẹ̀ bá nàró sí nǹkankan,

kò lè pa á mọ́ra.

21 Kì í jẹ àjẹṣẹ́kù,

nítorí náà, ọlá rẹ̀ kò le tọ́jọ́.

22 Ninu ọlá ńlá rẹ̀ yóo wà ninu àhámọ́,

ìbànújẹ́ yóo máa fi tagbára-tagbára bá a jà.

23 Dípò kí ó jẹun ní àjẹyó,

ibinu ńlá ni Ọlọrun yóo rán sí i,

tí yóo sì dà lé e lórí.

24 Bí ó bá ti ń sá fún idà,

bẹ́ẹ̀ ni ọfà bàbà yóo gún un ní àgúnyọ-lódì-keji.

25 Bí ó bá fa ọfà jáde kúrò lára rẹ̀,

tí ṣóńṣó orí ọfà jáde láti inú òróòro rẹ̀,

ìbẹ̀rùbojo yóo dé bá a.

26 Òkùnkùn biribiri ń dúró dè é,

iná tí eniyan kò dá ni yóo jó o ní àjórun,

ohun ìní tí ó kù ní ibùgbé rẹ̀ yóo sì parun.

27 Ọ̀run yóo fi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ hàn,

ilẹ̀ yóo dojú ìjà kọ ọ́.

28 Ibinu Ọlọrun gba àwọn ohun ìní rẹ̀ lọ,

àgbàrá ibinu yóo gbá wọn dànù.

29 Bẹ́ẹ̀ ni ìpín ẹni ibi yóo rí.

Ọlọrun ni ó ti yàn án bẹ́ẹ̀ láti ilẹ̀ wá.”

Categories
JOBU

JOBU 21

1 Jobu dáhùn pé,

2 “Ẹ fetí sí ọ̀rọ̀ mi dáradára,

kí ẹ sì jẹ́ kí ó jẹ́ ìtùnú fun yín.

3 Ẹ farabalẹ̀, kí ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi,

lẹ́yìn náà, ẹ lè máa fi mí ṣẹ̀sín ǹṣó.

4 Ṣé eniyan ni mò ń bá rojọ́ ni?

Kí ló dé tí n óo fi mú sùúrù?

5 Ẹ wò mí, kí ẹnu yà yín,

kí ẹ sì fọwọ́ bo ẹnu.

6 Nígbà tí mo ro ohun tí ó dé bá mi,

ẹ̀rù bà mí, mo sì wárìrì.

7 Kí ló dé tí eniyan burúkú fi wà láàyè,

tí ó di arúgbó, tí ó sì di alágbára?

8 Àwọn ọmọ wọn ati arọmọdọmọ wọn

di eniyan pataki pataki lójú ayé wọn.

9 Kò sí ìfòyà ninu ilé wọn,

bẹ́ẹ̀ ni Ọlọrun kò jẹ wọ́n níyà.

10 Àwọn mààlúù wọn ń gùn,

wọ́n sì ń bímọ ní àbíyè.

11 Wọn a máa kó àwọn ọmọ wọn jáde bí agbo ẹran,

àwọn ọmọ wọn a sì máa ṣe àríyá.

12 Wọn a máa fi aro, ìlù, ati fèrè kọrin,

wọn a sì máa yọ̀ sí ohùn dùùrù.

13 Wọn a máa gbé inú ọlá,

wọn a sì máa kú ikú alaafia.

14 Wọ́n ń sọ fún Ọlọrun pé, ‘Fi wá sílẹ̀!

A kò fẹ́ mọ òfin rẹ.

15 Ta ni Olodumare, tí a óo fi máa sìn ín?

Èrè wo ni ó wà níbẹ̀ fún wa bí à ń gbadura sí i?’

16 Wọ́n rò pé ìkáwọ́ wọn ni ọlà wọn wà,

nítèmi n kò lè tẹ̀lé ìmọ̀ràn àwọn eniyan burúkú.

17 “Ìgbà mélòó ni à ń pa fìtílà ẹni ibi?

Ìgbà mélòó ni iṣẹ́ ibi wọn ń dà lé wọn lórí?

Tabi tí Ọlọrun ṣe ìpín wọn ní ìrora ninu ibinu rẹ̀?

18 Ìgbà mélòó ni wọ́n dàbí àgékù koríko,

tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ kiri,

tabi bí ìyàngbò tí ìjì ń gbé lọ?

19 “O ní, ‘Ọlọrun ń to àìdára wọn jọ de àwọn ọmọ wọn.’

Jẹ́ kí ó dà á lé wọn lórí, kí wọ́n baà lè mọ ohun tí wọ́n ṣe.

20 Jẹ́ kí wọ́n fi ojú ara wọn rí ìparun ara wọn,

kí wọ́n sì rí ibinu Olodumare.

21 Kí ni ó kàn wọ́n pẹlu ilé wọn mọ́, lẹ́yìn tí wọn bá ti kú,

nígbà tí a bá ti ké ọjọ́ wọn kúrò lórí ilẹ̀.

22 Ṣé ẹnìkan lè kọ́ Ọlọrun ní ìmọ̀,

nígbà tí ó jẹ́ pé òun ni onídàájọ́ àwọn tí wọ́n wà ní ibi gíga?

23 Ẹnìkan kú ninu ọpọlọpọ ọrọ̀,

nítorí pé ó wà ninu ìdẹ̀ra ati àìfòyà,

24 ara rẹ̀ ń dán fún sísanra,

ara sì tù ú dé mùdùnmúdùn.

25 Ẹlòmíràn kú pẹlu ìbànújẹ́ ọkàn,

láìtọ́ ohun rere kankan wò rí.

26 Bákan náà ni gbogbo wọn ṣe sùn ninu erùpẹ̀,

tí ìdin sì bò wọ́n.

27 “Wò ó! Mo mọ èrò ọkàn yín,

mo sì mọ ète tí ẹ ní sí mi láti ṣe mí níbi.

28 Nítorí ẹ wí pé, ‘Níbo ni ilé àwọn eniyan ńlá wà;

níbo sì ni àgọ́ àwọn aṣebi wà?’

29 Ṣé ẹ kò tíì bèèrè ọ̀nà lọ́wọ́ àwọn arìnrìnàjò?

Ṣé ẹ kò sì tíì gba ẹ̀rí wọn, pé,

30 a dá ẹni ibi sí ní ọjọ́ ìdàrúdàpọ̀,

ati pé a gbà á là ní ọjọ́ ibinu?

31 Kò sẹ́ni tó jẹ́ fẹ̀sùn kan ẹni ibi lójú rẹ̀,

tabi kí ó gbẹ̀san nǹkan burúkú tí ó ṣe.

32 Nígbà tí a bá gbé e lọ sí itẹ́,

àwọn olùṣọ́ a máa ṣọ́ ibojì rẹ̀.

33 Ẹgbẹẹgbẹrun èrò a tẹ̀lé e lọ sí ibojì,

àìmọye eniyan a sì sin òkú rẹ̀;

kódà, ilẹ̀ á dẹ̀ fún un ní ibojì rẹ̀.

34 Nítorí náà, kí ni ìsọkúsọ tí ẹ lè fi tù mí ninu?

Kò sóhun tó kù ninu ọ̀rọ̀ yín,

tó ju irọ́ lọ.”

Categories
JOBU

JOBU 22

ÌFỌ̀RỌ̀WÉRỌ̀ KẸTA

1 Elifasi ará Temani bá dáhùn pé,

2 “Ǹjẹ́ eniyan lè wúlò fún Ọlọrun?

Nítòótọ́, bí eniyan tilẹ̀ jẹ́ ọlọ́gbọ́n, ara rẹ̀ ni ó wúlò fún.

3 Ǹjẹ́ jíjẹ́ olódodo rẹ̀ ṣe ohun rere kan fún Olodumare,

tabi kí ni èrè rẹ̀ bí ó bá jẹ́ ẹni pípé?

4 Ṣé nítorí pé o bẹ̀rù rẹ̀ ni ó ṣe bá ọ wí,

tí ó sì ń dá ọ lẹ́jọ́?

5 Ṣebí ìwà ibi rẹ ló pọ̀;

tí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ kò sì lópin?

6 O gba nǹkan ìdógò lọ́wọ́ àwọn arakunrin rẹ láìnídìí,

O bọ́ wọn sí ìhòòhò goloto.

7 O kò fún aláàárẹ̀ ní omi mu,

o kọ̀ láti fún ẹni tí ebi ń pa ní oúnjẹ.

8 Ẹni tí ó lágbára gba ilẹ̀,

ẹni tí ó lọ́lá sì ń gbé inú rẹ̀.

9 O lé àwọn opó jáde lọ́wọ́ òfo,

o sì ṣẹ́ aláìní baba lápá.

10 Nítorí náà ni okùn dídẹ fi yí ọ ká,

tí jìnnìjìnnì sì bò ọ́ lójijì.

11 Ìmọ́lẹ̀ rẹ ti di òkùnkùn, o kò ríran,

ìgbì omi sì bò ọ́ mọ́lẹ̀.

12 “Ṣebí Ọlọrun wà lókè ọ̀run

Ó ń wo àwọn ìràwọ̀ nísàlẹ̀

àní àwọn tí wọ́n ga jùlọ,

bí ó ti wù kí wọ́n ga tó!

13 Sibẹsibẹ ò ń bèèrè pé, ‘Kí ni Ọlọrun mọ̀?’

Ṣé ó lè ṣe ìdájọ́ láti inú òkùnkùn biribiri?

14 Ìkùukùu tí ó nípọn yí i ká,

tóbẹ́ẹ̀ tí kò lè ríran,

ó sì ń rìn ní òfuurufú ojú ọ̀run.

15 “Ṣé ọ̀nà àtijọ́ ni ìwọ óo máa tẹ̀lé;

ọ̀nà tí àwọn ẹni ibi rìn?

16 A gbá wọn dànù, kí àkókò wọn tó tó,

a ti gbá ìpìlẹ̀ wọn lọ.

17 Wọ́n sọ fún Ọlọrun pé,

‘Fi wá sílẹ̀, kí ni ìwọ Olodumare lè fi wá ṣe?’

18 Sibẹsibẹ ó fi ìṣúra dáradára kún ilé wọn–

ṣugbọn ìmọ̀ràn ẹni ibi jìnnà sí mi.

19 Àwọn olódodo rí i, inú wọn dùn,

àwọn aláìlẹ́bi fi wọ́n rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà,

20 wọ́n ń wí pé, ‘Dájúdájú, àwọn ọ̀tá wa ti parun,

iná sì ti jó gbogbo ohun tí wọ́n fi sílẹ̀.’

21 “Nisinsinyii gba ti Ọlọrun,

kí o sì wà ní alaafia;

kí ó lè dára fún ọ.

22 Gba ìtọ́ni rẹ̀,

kí o sì kó ọ̀rọ̀ rẹ̀ lékàn.

23 Bí o bá yipada sí Olodumare, tí o sì rẹ ara rẹ sílẹ̀,

tí o bá mú ìwà aiṣododo kúrò ní ibùgbé rẹ,

24 bí o bá ri wúrà mọ́ inú erùpẹ̀,

tí o fi wúrà Ofiri sí ààrin àwọn òkúta ìsàlẹ̀ odò,

25 bí Olodumare bá sì jẹ́ wúrà rẹ,

ati fadaka olówó iyebíye rẹ,

26 nígbà náà ni o óo láyọ̀ ninu Olodumare,

o óo sì lè dúró níwájú Ọlọrun.

27 Nígbà náà, o óo gbadura sí i, yóo sì gbọ́,

o óo sì san ẹ̀jẹ́ rẹ.

28 Ohunkohun tí o bá pinnu láti mú ṣe,

yóo ṣeéṣe fún ọ,

ìmọ́lẹ̀ yóo sì tàn sí ọ̀nà rẹ.

29 Nítorí Ọlọrun a máa rẹ onigbeeraga sílẹ̀,

a sì máa gba onírẹ̀lẹ̀.

30 A máa gba àwọn aláìṣẹ̀,

yóo sì gbà ọ́ là,

nípa ìwà mímọ́ rẹ.”

Categories
JOBU

JOBU 23

1 Nígbà náà ni Jobu dáhùn pé,

2 “Lónìí, ìráhùn mi tún kún fún ẹ̀dùn,

ọwọ́ Ọlọrun ń le lára mi,

bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mò ń kérora.

3 Áà! Ìbá jẹ́ pé mo mọ ibi tí mo ti lè rí i ni,

ǹ bá lọ siwaju ìtẹ́ rẹ̀!

4 Ǹ bá ro ẹjọ́ mi níwájú rẹ̀,

gbogbo ẹnu ni ǹ bá fi ṣàròyé.

5 Ǹ bá gbọ́ èsì tí yóo fún mi,

ati ọ̀rọ̀ tí yóo sọ fún mi.

6 Ṣé yóo gbéjà kò mí pẹlu agbára ńlá rẹ̀?

Rárá o, yóo gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu mi.

7 Ibẹ̀ ni olódodo yóo ti lè sọ ti ẹnu rẹ̀,

yóo sì dá mi sílẹ̀ títí lae.

8 “Wò ó! Mo lọ siwaju, kò sí níbẹ̀,

mo pada sẹ́yìn, n kò gbúròó rẹ̀.

9 Mo wo apá ọ̀tún, n kò rí i,

mo wo apá òsì, kò sí níbẹ̀.

10 Ṣugbọn ó mọ gbogbo ọ̀nà mi,

ìgbà tí ó bá dán mi wò tán,

n óo yege bíi wúrà.

11 Mò ń tẹ̀lé e lẹ́yìn, mo súnmọ́ ọn pẹ́kípẹ́kí,

n kò tíì yipada kúrò ní ọ̀nà rẹ̀.

12 N kò tíì yapa kúrò ninu àṣẹ tí ó ti ẹnu rẹ̀ jáde,

mò ń pa wọ́n mọ́ ninu ọkàn mi.

13 “Ṣugbọn Ọlọrun kìí yipada,

kò sí ẹni tí ó lè yí i lọ́kàn pada.

Ohun tí ó bá fẹ́ gan-an ni yóo ṣe.

14 Yóo ṣe ohun tí ó ti pinnu láti ṣe fún mi ní àṣeyọrí,

ati ọpọlọpọ nǹkan bẹ́ẹ̀ yòókù

tí ó tún ní lọ́kàn láti ṣe fún mi.

15 Ìdí nìyí tí ẹ̀rù fi bà mí níwájú rẹ̀,

tí mo bá ro nǹkan wọnyi, jìnnìjìnnì rẹ̀ a bò mí.

16 Ọlọrun ti kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọkàn mi,

Olodumare ti dẹ́rùbà mí.

17 Nítorí pé òkùnkùn yí mi ká,

òkùnkùn biribiri sì ṣú bò mí lójú.

Categories
JOBU

JOBU 24

1 “Kí ló dé tí Olodumare kò fi yan ọjọ́ ìdájọ́,

kí àwọn tí wọ́n mọ̀ ọ́n sì rí ọjọ́ náà?

2 “Àwọn eniyan a máa hú òkúta ààlà kúrò,

láti gba ilẹ̀ ẹlòmíràn kún tiwọn,

wọn a máa fi ipá sọ agbo ẹran ẹlòmíràn di tiwọn.

3 Wọn a kó kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ aláìníbaba lọ,

wọn a gba akọ mààlúù opó gẹ́gẹ́ bí ohun ìdógò.

4 Wọn a ti àwọn aláìní kúrò lójú ọ̀nà,

gbogbo àwọn talaka a sì lọ sápamọ́.

5 “Àwọn aláìní a máa ṣe làálàá káàkiri,

bíi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ inú aṣálẹ̀,

wọn a máa wá oúnjẹ fún àwọn ọmọ wọn ninu aṣálẹ̀.

6 Wọn a máa kó oúnjẹ jọ fún ẹran wọn ninu oko olóko

wọn a sì máa he èso àjàrà ní oko ìkà.

7 Wọn a máa sùn ní ìhòòhò ní gbogbo òru,

wọn kìí sìí rí aṣọ fi bora nígbà òtútù.

8 Òjò a pa wọ́n lórí òkè,

wọn a máa rọ̀ mọ́ àpáta nítorí àìsí ààbò.

9 (Àwọn kan ń já àwọn ọmọ aláìníbaba gbà lẹ́nu ọmú,

wọ́n sì ń gba ọmọ ọwọ́ lọ́wọ́ àwọn aláìní gẹ́gẹ́ bí ohun ìdógò.)

10 Àwọn aláìní ń rìn kiri ní ìhòòhò láìrí aṣọ wọ̀;

ebi ń pa wọ́n, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìtí ọkà ni wọ́n rù.

11 Wọ́n ń fún òróró lára èso olifi tí ó wà ní oko ìkà,

òùngbẹ sì ń gbẹ wọ́n, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọtí ni wọ́n ń pọn.

12 Àwọn tí wọn ń kú lọ ń kérora ní ìgboro,

àwọn tí a pa lára ń ké fún ìrànlọ́wọ́,

ṣugbọn Ọlọrun kò fetísí adura wọn.

13 “A rí àwọn tí wọ́n kọ ìmọ́lẹ̀,

tí wọn kò mọ ọ̀nà rẹ̀,

bẹ́ẹ̀ ni wọn kò dúró ní ọ̀nà náà.

14 Bí ilẹ̀ bá ṣú, apànìyàn á dìde,

kí ó lè pa talaka ati aláìní,

a sì dàbí olè ní òru.

15 Alágbèrè pàápàá ń ṣọ́ kí ilẹ̀ ṣú,

ó ń wí pé, ‘Kò sí ẹni tí yóo rí mi’;

ó fi ìbòjú bo ojú rẹ̀.

16 Lóru, wọn á máa lọ fọ́ ilé kiri,

ṣugbọn bí ilẹ̀ bá ti mọ́,

wọn á ti ìlẹ̀kùn mọ́rí,

wọn kì í rí ìmọ́lẹ̀.

17 Àárọ̀ ni òkùnkùn biribiri jẹ́ fún gbogbo wọn,

ọ̀rẹ́ wọn ni òkùnkùn biribiri tí ó bani lẹ́rù.”

18 Sofari dáhùn pé,

“O sọ wí pé,

‘Ìṣàn omi a máa gbá àwọn ẹni ibi lọ kíákíá;

ìpín tiwọn a sì di ìfibú ninu ilẹ̀ náà,

ẹnikẹ́ni kìí sì í lọ sinu ọgbà àjàrà wọn láti ṣiṣẹ́ mọ́.

19 Bí ọ̀gbẹlẹ̀ ati ooru ṣe máa ń mú kí omi yìnyín gbẹ

bẹ́ẹ̀ ni ibojì ṣe ń gbé àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ mì.

20 Wọn á gbàgbé wọn láàrin ìlú,

ẹnikẹ́ni kì í ranti orúkọ wọn mọ́,

bẹ́ẹ̀ ni ẹni ibi ṣe é wó lulẹ̀ bí ìtì igi.’

21 Wọ́n ń jẹ oúnjẹ àgàn tí kò bímọ,

wọn kò sì ṣe rere fún opó.

22 Sibẹsibẹ Ọlọrun fi ẹ̀mí gígùn fún alágbára nípa agbára rẹ̀;

wọn á gbéra nígbà tí ayé bá sú wọn.

23 Ọlọrun ń dáàbò bò wọ́n, ó ń ràn wọ́n lọ́wọ́,

ó sì ń pa wọ́n mọ́ ni ọ̀nà wọn.

24 A gbé wọn ga fún ìgbà díẹ̀,

lẹ́yìn náà, a rẹ̀ wọ́n sílẹ̀,

wọn á rọ, wọn á sì rẹ̀ dànù bí ewé,

a ké wọn kúrò bí orí ọkà bàbà.

25 Bí kò bá rí bẹ́ẹ̀, kí ẹnìkan já mi nírọ́,

kí ó sì fi hàn pé ìsọkúsọ ni mò ń sọ.”

Categories
JOBU

JOBU 25

1 Bilidadi ará Ṣuha bá dáhùn pé,

2 “Ọlọrun ni ọba, òun ló sì tó bẹ̀rù,

ó ń ṣe àkóso alaafia lọ́run.

3 Ta ló lè ka àwọn ọmọ ogun rẹ̀?

Ta ni ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ kò tàn sí?

4 Báwo wá ni eniyan ṣe lè jẹ́ olódodo níwájú Ọlọrun?

Báwo ni ẹni tí obinrin bí ṣe lè jẹ́ ẹni mímọ́?

5 Wò ó, òṣùpá pàápàá kò mọ́lẹ̀ tó,

bẹ́ẹ̀ ni àwọn ìràwọ̀ kò mọ́ tó lójú rẹ̀;

6 kí á má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ ti eniyan tí ó dàbí ìdin,

tabi ọmọ eniyan tí ó dàbí ekòló lásánlàsàn!”

Categories
JOBU

JOBU 26

1 Jobu bá dáhùn pé,

2 “Ìrànlọ́wọ́ wo ni ẹ ti ṣe fún àwọn tí wọn kò lágbára?

Aláìlera wo ni ẹ ti gbàlà?

3 Ìmọ̀ràn wo ni ẹ ti fún àwọn aláìgbọ́n?

Irú òye wo ni ẹ fihàn wọ́n?

4 Ta ló ń kọ yín ni ohun tí ẹ̀ ń sọ wọnyi?

Irú ẹ̀mí wo sì ní ń gba ẹnu yín sọ̀rọ̀?

5 “Àwọn òkú wárìrì nísàlẹ̀.

Omi ati àwọn olùgbé inú rẹ̀ pẹlu ń gbọ̀n rìrì.

6 Kedere ni isà òkú rí níwájú Ọlọrun,

bẹ́ẹ̀ ni ìparun kò farasin.

7 Ó na ìhà àríwá sórí òfuurufú,

ó sì so ayé rọ̀ sí òfuurufú.

8 Ó di omi papọ̀ ninu ìkùukùu rẹ̀ tí ó nípọn,

sibẹ ìkùukùu kò fà ya.

9 Ó dí ojú òṣùpá,

ó sì fi ìkùukùu bò ó.

10 Ó ṣe òbìrìkítí kan sórí omi,

ó fi ṣe ààlà láàrin òkùnkùn ati ìmọ́lẹ̀.

11 Àwọn òpó ọ̀run mì tìtì,

wọ́n sì wárìrì nítorí ìbáwí rẹ̀.

12 Nípa agbára rẹ̀, ó mú kí òkun parọ́rọ́,

nípa ìmọ̀ rẹ̀, ó pa Rahabu.

13 Ó fi afẹ́fẹ́ ṣe ojú ọ̀run lọ́ṣọ̀ọ́;

ọwọ́ ló fi pa ejò tí ń fò.

14 Ṣugbọn kékeré nìyí ninu agbára rẹ̀,

díẹ̀ ni a tíì gbọ́ nípa iṣẹ́ rẹ̀!

Nítorí náà ta ló lè mọ títóbi agbára rẹ̀?”