Categories
LEFITIKU

LEFITIKU 8

Ìyàsímímọ́ Aaroni ati Àwọn Ọmọ Rẹ̀

1 OLUWA sọ fún Mose pé,

2 “Mú Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin ati ẹ̀wù iṣẹ́ alufaa wọn, ati òróró ìyàsímímọ́, ati akọ mààlúù fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ati àgbò meji náà, ati agbọ̀n burẹdi tí kò ní ìwúkàrà.

3 Lẹ́yìn náà, kó gbogbo àwọn eniyan náà jọ sí ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ.”

4 Mose bá pe gbogbo ìjọ eniyan náà jọ sí ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún un.

5 Ó sọ fún wọn pé, “Ohun tí OLUWA pàṣẹ pé ẹ gbọdọ̀ ṣe nìyí.”

6 Ó mú Aaroni, ati àwọn ọmọ rẹ̀ jáde, ó fi omi wẹ̀ wọ́n.

7 Ó gbé ẹ̀wù náà wọ Aaroni, ó sì dì í ní àmùrè rẹ̀, ó gbé aṣọ àwọ̀kanlẹ̀ wọ̀ ọ́ ati efodu rẹ̀, ó sì fi ọ̀já efodu tí wọ́n ṣe iṣẹ́ ọnà dáradára sí lára dì í lámùrè.

8 Ó mú ìgbàyà, ó so ó mọ́ ọn láyà, ó sì fi Urimu ati Tumimu sí ara ìgbàyà náà.

9 Ó fi fìlà dé e lórí, ó fi ohun ọ̀ṣọ́ wúrà, adé mímọ́ tíí ṣe àmì ìyàsímímọ́, sí iwájú fìlà náà, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pa á láṣẹ fún Mose.

10 Mose gbé òróró ìyàsímímọ́, ó ta á sí gbogbo ara Àgọ́ náà ati ohun gbogbo tí ó wà ninu rẹ̀, ó sì yà wọ́n sí mímọ́.

11 Ó mú lára òróró náà ó wọ́n ọn sí ara pẹpẹ nígbà meje, ó ta á sórí pẹpẹ náà ati gbogbo àwọn ohun èlò tí wọ́n wà níbẹ̀, ati agbada omi ati ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀; ó fi yà wọ́n sí mímọ́.

12 Ó ta díẹ̀ ninu òróró náà sí Aaroni lórí láti yà á sí mímọ́.

13 Mose kó àwọn ọmọ Aaroni, ó wọ̀ wọ́n lẹ́wù, ó sì dì wọ́n ní àmùrè, ó dé wọn ní fìlà, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún un.

14 Lẹ́yìn náà, ó mú mààlúù ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ jáde, Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin gbé ọwọ́ lé e lórí.

15 Mose pa mààlúù náà, ó gbé ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ó ti ìka bọ̀ ọ́, ó sì fi sí ara àwọn ìwo pẹpẹ yípo, ó fi yà wọ́n sí mímọ́. Ó da ẹ̀jẹ̀ yòókù sídìí pẹpẹ fún ètùtù, bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe yà wọ́n sí mímọ́.

16 Lẹ́yìn náà, ó mú gbogbo ọ̀rá tí ó bo àwọn nǹkan inú mààlúù náà, ati ẹ̀dọ̀ rẹ̀, ati kíndìnrín rẹ̀ mejeeji, pẹlu ọ̀rá tó wà lára wọn, ó sun wọ́n lórí pẹpẹ.

17 Ṣugbọn ó dáná sun ara ẹran akọ mààlúù náà, ati awọ rẹ̀, ati ìgbẹ́ rẹ̀ lẹ́yìn ibùdó náà, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún un.

18 Lẹ́yìn náà, Mose fa àgbò ẹbọ sísun kalẹ̀, Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin sì gbé ọwọ́ wọn lé e lórí.

19 Lẹ́yìn náà, Mose pa á, ó da ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sórí pẹpẹ yípo.

20 Wọ́n gé ẹran àgbò náà sí wẹ́wẹ́, ó sun gbogbo rẹ̀ pẹlu orí rẹ̀ ati ọ̀rá rẹ̀ lórí pẹpẹ.

21 Nígbà tí ó fọ nǹkan inú rẹ̀ ati ẹsẹ̀ rẹ̀, ó fi gbogbo rẹ̀ rú ẹbọ sísun, ẹbọ olóòórùn dídùn tí a fi iná sun sí OLUWA, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose.

22 Lẹ́yìn náà, ó fa àgbò keji kalẹ̀, èyí tí í ṣe àgbò ìyàsímímọ́. Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ gbé ọwọ́ wọn lé e lórí.

23 Lẹ́yìn náà Mose pa á, ó tọ́ ninu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ó fi kan etí ọ̀tún Aaroni, ati àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, ati àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún rẹ̀.

24 Wọ́n mú àwọn ọmọ Aaroni náà jáde, Mose tọ́ ninu ẹ̀jẹ̀ náà, ó fi kan etí ọ̀tún wọn, ati àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún wọn, ati àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún wọn, ó sì da ẹ̀jẹ̀ yòókù sórí pẹpẹ yípo.

25 Lẹ́yìn náà, ó mú ọ̀rá àgbò náà, ati ọ̀rá ìrù rẹ̀, ati gbogbo ọ̀rá tí ó bo àwọn nǹkan inú rẹ̀, ati ẹ̀dọ̀ rẹ̀, ati kíndìnrín rẹ̀ mejeeji pẹlu ọ̀rá tí ó wà lára wọn, ati itan ọ̀tún rẹ̀.

26 Ó mú burẹdi dídùn kan tí kò ní ìwúkàrà ninu, ninu agbọ̀n burẹdi tí ó wà níwájú OLUWA, ati burẹdi olóròóró kan tí kò ní ìwúkàrà ninu ati burẹdi fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ kan, ó kó wọn lé orí ọ̀rá náà ati itan ọ̀tún àgbò náà.

27 Ó kó gbogbo rẹ̀ lé Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́, wọ́n sì fì wọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì níwájú OLUWA.

28 Lẹ́yìn náà, Mose gbà á kúrò lọ́wọ́ wọn, ó sun wọ́n lórí pẹpẹ, pẹlu ẹbọ sísun bí ẹbọ ìyàsímímọ́, ẹbọ olóòórùn dídùn, tí a fi iná sun sí OLÚWA.

29 Mose mú igẹ̀ àyà àgbò náà, ó fì í gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì níwájú OLUWA. Òun ni ìpín Mose ninu àgbò ìyàsímímọ́ yìí, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pa á láṣẹ fún un.

30 Lẹ́yìn náà, Mose mú ninu òróró ìyàsímímọ́, ati díẹ̀ ninu ẹ̀jẹ̀ tí ó wà lórí pẹpẹ, ó wọ́n ọn sí ara Aaroni ati aṣọ rẹ̀, ati sí ara àwọn ọmọ rẹ̀, ati aṣọ wọn. Bẹ́ẹ̀ ló ṣe ya Aaroni ati àwọn aṣọ rẹ̀ sí mímọ́, ati àwọn ọmọ rẹ̀, tàwọn taṣọ wọn.

31 Mose bá sọ fún Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin pé, “Ẹ lọ bọ ẹran àgbò náà lẹ́nu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ kí ẹ sì jẹ ẹ́ níbẹ̀, pẹlu burẹdi tí ó wà ninu agbọ̀n ọrẹ ẹbọ ìyàsímímọ́, gẹ́gẹ́ bí mo ti pa á láṣẹ pé: ‘Aaroni ati ọmọ rẹ̀ ni kí wọ́n máa jẹ ẹ́’.

32 Ohunkohun tí ó bá kù ninu ẹran ati burẹdi náà, ẹ dáná sun ún.

33 Ẹ kò sì gbọdọ̀ jáde kúrò ní ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ náà fún ọjọ́ meje títí tí ọjọ́ ètò ìyàsímímọ́ yín yóo fi pé; nítorí ọjọ́ meje gbáko ni ètò ìyàsímímọ́ yín yóo gbà.

34 Gbogbo bí a ti ṣe lónìí ni OLUWA pa láṣẹ pé kí á ṣe, láti ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ yín.

35 Lẹ́nu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ ni kí ẹ wà tọ̀sán-tòru fún ọjọ́ meje, kí ẹ máa ṣe àwọn ohun tí OLUWA pa láṣẹ fun yín, kí ẹ má baà kú; nítorí pé bẹ́ẹ̀ ni ó pa á láṣẹ fún mi.”

36 Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ sì ṣe gbogbo ohun tí OLUWA pa láṣẹ láti ẹnu Mose.

Categories
LEFITIKU

LEFITIKU 9

Aaroni Rúbọ sí OLUWA

1 Ní ọjọ́ kẹjọ, Mose pe Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ ati àwọn àgbààgbà Israẹli;

2 ó wí fún Aaroni pé, “Mú ọ̀dọ́ akọ mààlúù kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ati àgbò kan fún ẹbọ sísun kí o sì fi wọ́n rúbọ níwájú OLUWA. Àwọn ẹran mejeeji yìí kò gbọdọ̀ ní àbààwọ́n.

3 Sì sọ fún àwọn eniyan Israẹli pé, ‘Ẹ mú òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ati ọmọ mààlúù kan ati ọ̀dọ́ aguntan kan fún ẹbọ sísun, kí àwọn mejeeji jẹ́ ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan, wọn kò sì gbọdọ̀ ní àbààwọ́n.

4 Sì mú akọ mààlúù kan ati àgbò kan fún ẹbọ alaafia, kí ẹ fi wọ́n rúbọ níwájú OLUWA pẹlu ẹbọ ohun jíjẹ tí a fi òróró pò, nítorí pé OLUWA yóo fi ara hàn yín lónìí.’ ”

5 Wọ́n mú àwọn ohun tí Mose paláṣẹ wá siwaju Àgọ́ Àjọ, gbogbo ìjọ eniyan sì dúró níwájú OLUWA.

6 Mose sọ fún wọn pé, “Ohun tí OLUWA paláṣẹ fun yín láti ṣe nìyí, ògo OLUWA yóo hàn sí yín.”

7 Lẹ́yìn náà, Mose sọ fún Aaroni pé, “Súnmọ́ ibi pẹpẹ, kí o sì rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ rẹ, ati ẹbọ sísun rẹ, kí o sì ṣe ètùtù fún ara rẹ ati fún àwọn eniyan náà. Gbé ẹbọ àwọn eniyan náà wá, kí o sì ṣe ètùtù fún wọn, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pa á láṣẹ.”

8 Aaroni bá súnmọ́ ibi pẹpẹ náà, ó pa ọ̀dọ́ mààlúù fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ fún ara rẹ̀.

9 Àwọn ọmọ rẹ̀ sì gbé ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wá fún un, ó sì ti ìka bọ̀ ọ́, ó fi kan ara ìwo pẹpẹ, ó sì da ẹ̀jẹ̀ yòókù sí ìdí pẹpẹ.

10 Ó mú ọ̀rá ọ̀dọ́ mààlúù náà, ati àwọn kíndìnrín rẹ̀ ati ẹ̀dọ̀ rẹ̀ kúrò ninu ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ó sun wọ́n lórí pẹpẹ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose.

11 Ó sì dáná sun ẹran ati awọ mààlúù náà lẹ́yìn ibùdó.

12 Ó pa ẹran ẹbọ sísun, àwọn ọmọ rẹ̀ sì gbé ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ tọ̀ ọ́ lọ, ó sì dà á sí ara pẹpẹ yípo.

13 Wọ́n gbé ẹran ẹbọ sísun tí wọ́n ti gé sí wẹ́wẹ́, ati orí rẹ̀ tọ̀ ọ́ lọ, ó sì sun wọ́n lórí pẹpẹ.

14 Ó fọ àwọn nǹkan inú rẹ̀, ati ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì sun wọ́n papọ̀ pẹlu ẹbọ sísun lórí pẹpẹ.

15 Lẹ́yìn náà ó fa ẹran ẹbọ sísun àwọn eniyan náà kalẹ̀, ó mú ewúrẹ́ ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ àwọn eniyan náà, ó pa á, ó sì fi rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ wọn, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ti ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ti àkọ́kọ́.

16 Ó gbé ẹran ẹbọ sísun wá, ó sì fi rúbọ gẹ́gẹ́ bí ìlànà.

17 Ó gbé ẹbọ ohun jíjẹ wá, ó bu ẹ̀kúnwọ́ kan ninu rẹ̀, ó sì sun ún lórí pẹpẹ ní ẹ̀gbẹ́ ẹbọ sísun ti òwúrọ̀.

18 Ó pa akọ mààlúù ati àgbò ẹbọ alaafia fún àwọn eniyan, àwọn ọmọ rẹ̀ gbé ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, ó sì dà á sórí pẹpẹ náà yípo.

19 Ó mú ọ̀rá akọ mààlúù, ati ti àgbò náà, pẹlu ìrù wọn tí ó lọ́ràá, ati ọ̀rá tí ó bo àwọn nǹkan inú wọn, ati kíndìnrín ati ẹ̀dọ̀ wọn.

20 Ó kó gbogbo ọ̀rá náà lé orí igẹ̀ ẹran náà; ó sun ún lórí pẹpẹ.

21 Ṣugbọn ó mú àwọn igẹ̀ ẹran náà ati itan ọ̀tún wọn, ó fì wọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì níwájú OLUWA, bí Mose ti pa á láṣẹ.

22 Lẹ́yìn náà, Aaroni kọjú sí àwọn eniyan náà, ó gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè, ó sì súre fún wọn. Lẹ́yìn náà, ó sọ̀kalẹ̀ láti ibi tí ó ti ń rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ati ẹbọ sísun ati ẹbọ alaafia.

23 Mose ati Aaroni bá wọ inú Àgọ́ Àjọ lọ. Nígbà tí wọ́n jáde, wọ́n súre fún àwọn eniyan náà, ògo OLUWA sì yọ sí gbogbo wọn.

24 Lójijì, iná ṣẹ́ láti ọ̀dọ̀ OLUWA wá, ó jó ẹbọ sísun náà, ati ọ̀rá tí ó wà lórí pẹpẹ. Nígbà tí gbogbo àwọn eniyan rí i, wọ́n kígbe sókè, wọ́n sì dojúbolẹ̀.

Categories
LEFITIKU

LEFITIKU 10

Ẹ̀ṣẹ̀ Nadabu ati Abihu

1 Àwọn ọmọ Aaroni meji kan, ọkunrin, tí wọn ń jẹ́ Nadabu ati Abihu, mú àwo turari wọn, olukuluku fọn ẹ̀yinná sinu tirẹ̀, wọ́n da turari lé e lórí, wọ́n sì fi rúbọ níwájú OLUWA, ṣugbọn iná yìí kì í ṣe irú iná mímọ́ tí OLUWA pa láṣẹ fún wọn.

2 OLUWA bá rán iná kan jáde, iná náà jó wọn pa, wọ́n sì kú níwájú OLUWA.

3 Mose bá pe Aaroni, ó wí fún un pé, “Ohun tí OLUWA wí nìyí, ‘N óo fi ara mi hàn gẹ́gẹ́ bí ẹni mímọ́ láàrin àwọn tí wọ́n jẹ́ òjíṣẹ́ mi, n óo sì gba ògo níwájú gbogbo àwọn eniyan’ ” Aaroni dákẹ́, kò sọ̀rọ̀.

4 Mose bá pe Miṣaeli ati Elisafani, àwọn ọmọ Usieli, arakunrin Aaroni, ó ní, “Ẹ lọ gbé òkú àwọn arakunrin yín kúrò níwájú ibi mímọ́, kí ẹ sì gbé wọn jáde kúrò láàrin ibùdó.”

5 Wọ́n bá gbé wọn tẹ̀wù tẹ̀wù kúrò láàrin ibùdó gẹ́gẹ́ bí Mose ti wí.

6 Mose sọ fún Aaroni, ati àwọn ọmọ rẹ̀ meji, Eleasari ati Itamari pé, “Ẹ má ṣe fi irun yín sílẹ̀ játijàti, ẹ má sì ṣe fa aṣọ yín ya (láti fihàn pé ẹ̀ ń ṣọ̀fọ̀), kí ẹ má baà kú, kí ibinu OLUWA má baà wá sórí gbogbo eniyan. Ṣugbọn gbogbo ilé Israẹli, àwọn eniyan yín, lè ṣọ̀fọ̀ iná tí OLUWA fi jó yín.

7 Ẹ kò sì gbọdọ̀ jáde kúrò ní ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ, kí ẹ má baà kú, nítorí pé òróró ìyàsímímọ́ OLUWA wà lórí yín.” Wọ́n sì ṣe bí Mose ti wí.

Òfin fún Àwọn Alufaa

8 OLUWA bá Aaroni sọ̀rọ̀, ó ní,

9 “Nígbà tí o bá ń wọ inú Àgọ́ Àjọ lọ, ìwọ, ati àwọn ọmọ rẹ, ẹ kò gbọdọ̀ mu ọtí waini tabi ọtí líle, kí ẹ má baà kú; èyí yóo jẹ́ ìlànà títí ayé fún arọmọdọmọ yín.

10 Ẹ gbọdọ̀ mọ ìyàtọ̀, láàrin ohun tí a yà sọ́tọ̀ fún OLUWA ati ohun tí ó wà fún ìlò gbogbo eniyan; ẹ níláti mọ ìyàtọ̀, láàrin àwọn ohun tí wọ́n jẹ́ mímọ́ ati àwọn ohun tí wọ́n jẹ́ aláìmọ́;

11 ẹ sì níláti kọ́ àwọn eniyan Israẹli ní gbogbo ìlànà tí OLUWA ti là sílẹ̀, tí ó ní kí Mose sọ fun yín.”

12 Mose sọ fún Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ mejeeji tí wọ́n ṣẹ́kù, Eleasari ati Itamari, ó ní, “Ẹ gbé ohun ìrúbọ tí ó kù ninu ẹbọ ohun jíjẹ tí a fi iná sun sí OLUWA, kí ẹ sì jẹ ẹ́ lẹ́bàá pẹpẹ, láì fi ìwúkàrà sí i, nítorí pé mímọ́ jùlọ ni.

13 Ibi mímọ́ ni kí ẹ ti jẹ ẹ́, nítorí pé òun ni ìpín yín ati ti àwọn ọmọ yín, ninu ẹbọ sísun OLUWA, nítorí pé bẹ́ẹ̀ ni OLUWA pa á láṣẹ fún mi.

14 Ṣugbọn kí ẹ jẹ igẹ̀ tí ẹ bá fi rú ẹbọ fífì ati itan ẹran tí wọ́n fi rú ẹbọ ní ibi mímọ́, ìwọ ati àwọn ọmọkunrin rẹ ati àwọn ọmọbinrin rẹ, nítorí pé ìpín tìrẹ ni, ati ti àwọn ọmọkunrin rẹ, ninu ẹbọ alaafia, tí àwọn eniyan Israẹli rú.

15 Nígbà tí wọ́n bá mú ọ̀rá ẹran wá fún ẹbọ sísun, tí wọ́n mú itan ẹran tí wọ́n fi rúbọ, ati igẹ̀ àyà rẹ̀ fún ẹbọ fífì níwájú OLUWA, yóo máa jẹ́ tìrẹ, ati ti àwọn ọmọ rẹ, gẹ́gẹ́ bí ìpín yín títí ayé, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pa á láṣẹ.”

16 Mose fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ wádìí nípa ewúrẹ́ tí wọ́n fi rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ó sì rí i pé wọ́n ti dáná sun ún. Inú bí i sí Eleasari ati Itamari, àwọn ọmọ Aaroni tí wọ́n ṣẹ́kù, ó ní,

17 “Kí ló dé tí ẹ kò fi jẹ ẹran ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ní ibi mímọ́ nígbà tí ó jẹ́ pé, ohun tí ó mọ́ jùlọ ni, tí ó sì jẹ́ pé ẹ̀yin ni OLUWA ti fún, kí ẹ lè máa ru ẹ̀ṣẹ̀ ìjọ eniyan yìí, kí ẹ sì máa ṣe ètùtù fún wọn níwájú OLUWA.

18 Wọn kò sì tíì gbé ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wá sinu ibi mímọ́, gẹ́gẹ́ bí mo ti pa á láṣẹ.”

19 Aaroni dá Mose lóhùn pé, “Wò ó! Lónìí ni wọ́n rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ati ẹbọ sísun wọn sí OLUWA, sibẹsibẹ irú nǹkan yìí ṣẹlẹ̀ sí mi. Bí ó bá jẹ́ pé mo ti jẹ ẹran ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ lónìí ni, ǹjẹ́ ẹbọ náà lè jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà níwájú OLUWA?”

20 Nígbà tí Mose gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, inú rẹ̀ rọ̀.

Categories
LEFITIKU

LEFITIKU 11

Àwọn Ẹranko Tí Ó Tọ̀nà láti Jẹ

1 OLUWA rán Mose ati Aaroni pé

2 kí wọ́n sọ fún àwọn eniyan Israẹli pé, “Àwọn ẹran tí wọ́n lè jẹ lára àwọn ẹran tí wọ́n wà láyé nìwọ̀nyí:

3 Àwọn ẹran tí wọ́n bá ya pátákò ẹsẹ̀, àwọn tí ẹsẹ̀ wọ́n là ati àwọn tí wọn ń jẹ àpọ̀jẹ.

4 Ninu àwọn tí wọn ń jẹ àpọ̀jẹ tabi tí pátákò ẹsẹ̀ wọ́n yà, ẹ kò gbọdọ̀ jẹ àwọn wọnyi: ràkúnmí, nítorí pé ó ń jẹ àpọ̀jẹ, ṣugbọn pátákò ẹsẹ̀ rẹ̀ kò yà, ó jẹ́ ohun àìmọ́ fun yín.

5 Ati gara nítorí pé ó ń jẹ àpọ̀jẹ, ṣugbọn pátákò ẹsẹ̀ rẹ̀ kò yà, ó jẹ́ ohun àìmọ́ fun yín.

6 Ati ehoro, nítorí pé ó ń jẹ àpọ̀jẹ, ṣugbọn pátákò ẹsẹ̀ rẹ̀ kò yà, ó jẹ́ ohun àìmọ́ fun yín.

7 Ati ẹlẹ́dẹ̀ nítorí pé pátákò ẹsẹ̀ rẹ̀ yà, ẹsẹ̀ rẹ̀ sì yà, ṣugbọn kì í jẹ àpọ̀jẹ, ó jẹ́ ohun àìmọ́ fun yín.

8 Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹran wọn, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọdọ̀ fọwọ́ kan òkú wọn, aláìmọ́ ni wọ́n.

9 “Ninu àwọn ẹ̀dá alààyè tí ń gbé inú omi, ẹ lè jẹ àwọn wọnyi: gbogbo ohun tí ó bá ní lẹbẹ ati ìpẹ́, kì báà jẹ́ èyí tí ó ń gbé inú òkun tabi inú odò, ẹ lè jẹ wọ́n.

10 Ṣugbọn ohunkohun tí ó ń gbé inú òkun, tabi inú odò, ninu gbogbo àwọn ẹ̀dá alààyè tí wọn ń káàkiri inú omi, èyíkéyìí tí kò bá ní lẹbẹ ati ìpẹ́, ohun ìríra ni fun yín.

11 Ohun ìríra ni wọn yóo jẹ́ fun yín, ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹran wọn, ohun ìríra ni òkú wọn gbọdọ̀ jẹ́ fun yín pẹlu.

12 Ohunkohun tí ó ń gbé inú omi, tí kò bá ti ní lẹbẹ ati ìpẹ́, ohun ìríra ni fun yín.

13 “Àwọn wọnyi ni ẹ óo kà sí ohun ìríra, tí ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ninu àwọn ẹyẹ: idì, igún, ati oríṣìí àṣá kan tí ó dàbí idì,

14 gbogbo oniruuru àṣá,

15 gbogbo oniruuru ẹyẹ ìwò,

16 ògòǹgò, ati ẹyẹ kan bí ẹ̀lulùú tí ń gbé aṣálẹ̀,

17 ẹyẹ òwìwí, ẹyẹ òòyo, ati ẹyẹ kan bí igún,

18 ògbúgbú, òfú, ati àkàlà,

19 ẹyẹ àkọ̀, ati oniruuru yanjayanja, ẹyẹ atọ́ka, ati àdán.

20 “Gbogbo kòkòrò tí ó ní ìyẹ́, tí ó sì ń fi ẹsẹ̀ mẹrẹẹrin rìn, ìríra ni wọ́n jẹ́ fun yín.

21 Sibẹsibẹ ninu àwọn kòkòrò tí wọn ní ìyẹ́, tí wọn ń fi ẹsẹ̀ mẹrẹẹrin rìn, ẹ lè jẹ àwọn tí wọn bá ní tete tí wọ́n fi ń ta káàkiri lórí ilẹ̀.

22 Ẹ lè jẹ àwọn wọnyi ninu wọn: Oríṣìíríṣìí eṣú ati oríṣìíríṣìí ìrẹ̀ ati oríṣìíríṣìí tata.

23 Ṣugbọn gbogbo àwọn kòkòrò yòókù tí wọ́n ní ìyẹ́ tí wọ́n sì ní ẹsẹ̀ mẹrin, ìríra ni wọ́n jẹ́ fun yín.

24 “Àwọn ni wọ́n lè sọ yín di aláìmọ́; ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ọwọ́ kan òkú wọn yóo di aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.

25 Bí ẹnikẹ́ni bá gbé òkú wọn, kí ẹni náà fọ aṣọ rẹ̀, yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.

26 Gbogbo ẹranko tí pátákò ẹsẹ̀ wọn bá là, ṣugbọn tí ẹsẹ̀ wọn kò là, tí wọn kì í sì í jẹ àpọ̀jẹ, aláìmọ́ ni wọ́n; ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ọwọ́ kàn wọ́n di aláìmọ́.

27 Ninu àwọn ẹranko tí wọ́n ń fi ẹsẹ̀ mẹrin rìn, gbogbo àwọn tí wọ́n bá ti ń fi ẹsẹ̀ mẹrẹẹrin rìn tí wọ́n sì ní èékánná jẹ́ aláìmọ́ fun yín; ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ọwọ́ kan òkú wọn yóo di aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.

28 Bí ẹnikẹ́ni bá gbé òkú wọn, kí ó fọ aṣọ rẹ̀, yóo sì jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́; ohun àìmọ́ ni wọ́n jẹ́ fun yín.

29 “Àwọn tí wọ́n jẹ́ aláìmọ́ fun yín ninu gbogbo àwọn ohun tí ń rìn lórí ilẹ̀ ni: asín, ati èkúté, ati àwọn oríṣìíríṣìí aláǹgbá ńlá,

30 ọmọọ́lé, ọ̀ni, aláǹgbá, agílíńtí ati alágẹmọ.

31 Wọ́n jẹ́ aláìmọ́ fun yín ninu gbogbo ohun tí ń rìn lórí ilẹ̀, ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ọwọ́ kan òkú wọn di aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.

32 Ohunkohun tí òkú wọn bá jábọ́ lé lórí di aláìmọ́, ìbáà jẹ́ ohun èlò igi, tabi aṣọ tabi awọ, tabi àpò, irú ohun èlò yòówù tí ó lè jẹ́, ó níláti di fífọ̀, yóo sì jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́, lẹ́yìn náà, yóo di mímọ́.

33 Bí èyíkéyìí ninu wọn bá jábọ́ sórí ohun èlò amọ̀, gbogbo ohun tí ó bá wà ninu ohun èlò amọ̀ náà di aláìmọ́, fífọ́ ni kí o fọ́ ohun èlò náà.

34 Ohunkohun tí ó bá jẹ́ jíjẹ tí ó bá wà ninu ìkòkò amọ̀ yìí, tabi tí omi inú rẹ̀ bá ta sí lára, di aláìmọ́, ohunkohun tí ó bá jẹ́ mímu, tí ó wà ninu rẹ̀ náà di aláìmọ́.

35 Ohunkohun tí apákan ninu òkú wọn bá jábọ́ lé lórí di aláìmọ́, kì báà jẹ́ ààrò tabi àdògán, o gbọdọ̀ fọ́ ọ túútúú; wọ́n jẹ́ aláìmọ́, wọ́n sì gbọdọ̀ jẹ́ aláìmọ́ fun yín.

36 Tí ó bá jẹ́ odò, tabi kànga tí ó ní omi ni, wọn kì í ṣe aláìmọ́, ṣugbọn gbogbo nǹkan yòókù tí ó fara kan òkú wọn di aláìmọ́.

37 Bí apákan ninu òkú wọn bá jábọ́ lé orí èso tí eniyan fẹ́ gbìn, èso náà kò di aláìmọ́.

38 Ṣugbọn bí eniyan bá da omi lé èso náà lórí, tí apákan ninu òkú wọn sì já lé èso náà, ó di aláìmọ́ fun yín.

39 “Bí ọ̀kankan ninu àwọn ẹran tí ẹ lè jẹ bá kú, ẹnikẹ́ni tí ó bá fara kan òkú rẹ̀ di aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.

40 Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ òkú ẹran náà níláti fọ aṣọ rẹ̀, yóo sì jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́. Ẹni tí ó bá ru òkú ẹran náà gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, yóo sì jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà.

41 “Ohunkohun tí ń fi àyà fà lórí ilẹ̀ ayé jẹ́ ìríra, ẹnikẹ́ni kò sì gbọdọ̀ jẹ ẹ́.

42 Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ohunkohun tí ó bá ń fi àyà wọ́, tabi ohunkohun tí ó bá ń fi ẹsẹ̀ mẹrin rìn tabi ohunkohun tí ó ní ọpọlọpọ ẹsẹ̀, tabi ohunkohun tí ó ń fà lórí ilẹ̀, nítorí ohun ìríra ni wọ́n.

43 Ẹ kò gbọdọ̀ fi ohunkohun tí ń fi àyà fà lórí ilẹ̀ sọ ara yín di ìríra; ẹ kò gbọdọ̀ kó ẹ̀gbin bá ara yín, kí ẹ má baà di aláìmọ́.

44 Nítorí pé, èmi ni OLUWA Ọlọrun yín, ẹ ya ara yín sí mímọ́, kí ẹ sì jẹ́ mímọ́, nítorí mímọ́ ni èmi Ọlọrun. Ẹ kò gbọdọ̀ fi ohunkohun tí ń fi àyà fà lórí ilẹ̀ sọ ara yín di aláìmọ́.

45 Nítorí èmi ni OLUWA tí ó ko yín jáde láti ilẹ̀ Ijipti wá, láti jẹ́ Ọlọrun yín; nítorí náà, ẹ níláti jẹ́ mímọ́, nítorí pé, mímọ́ ni èmi Ọlọrun.”

46 Èyí ni òfin tí ó jẹ mọ́ àwọn ẹranko ati ẹyẹ ati àwọn ẹ̀dá alààyè tí wọn wà ninu omi ati àwọn ẹ̀dá alààyè tí wọ́n ń fi àyà fà lórí ilẹ̀,

47 láti fi ìyàtọ̀ sí ààrin ohun tí ó mọ́, ati ohun tí kò mọ́, ati sí ààrin ẹ̀dá alààyè tí eniyan lè jẹ, ati ẹ̀dá alààyè tí eniyan kò gbọdọ̀ jẹ.

Categories
LEFITIKU

LEFITIKU 12

Ìwẹ̀nùmọ́ Àwọn Obinrin Lẹ́yìn Ìbímọ

1 OLUWA ní kí Mose

2 sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Bí obinrin kan bá lóyún tí ó sì bí ọmọkunrin, ó di aláìmọ́ fún ọjọ́ meje, gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ aláìmọ́ nígbà tí ó bá ń ṣe nǹkan oṣù rẹ̀.

3 Tí ó bá di ọjọ́ kẹjọ, wọn yóo kọ ilà abẹ́ fún ọmọ náà.

4 Obinrin náà yóo wà ninu ẹ̀jẹ̀ ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀ fún ọjọ́ mẹtalelọgbọn; kò gbọdọ̀ fi ọwọ́ kan ohun mímọ́ kan, bẹ́ẹ̀ ni kò sì gbọdọ̀ wá sinu ibi mímọ́, títí tí ọjọ́ ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀ yóo fi pé.

5 “Ṣugbọn bí ó bá jẹ́ pé obinrin ni ó bí, ọ̀sẹ̀ meji ni yóo fi wà ní ipò àìmọ́ bí ó ti jẹ́ aláìmọ́ nígbà tí ó bá ń ṣe nǹkan oṣù rẹ̀; yóo sì wà ninu ẹ̀jẹ̀ ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀ fún ọjọ́ mẹrindinlaadọrin.

6 “Nígbà tí ọjọ́ ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀ bá pé, kì báà ṣe fún ọmọkunrin tabi fún ọmọbinrin, yóo mú ọ̀dọ́ aguntan ọlọ́dún kan wá sí ọ̀dọ̀ alufaa ní ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ fún ẹbọ sísun, kí ó sì mú yálà ọmọ ẹyẹlé tabi àdàbà wá, fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀.

7 Alufaa yóo sì fi rúbọ níwájú OLUWA, yóo ṣe ètùtù fún un; nígbà náà ni yóo di mímọ́ kúrò ninu ìṣàn ẹ̀jẹ̀ rẹ̀. Òfin yìí wà fún obinrin tí ó bá bímọ, kì báà jẹ́ ọmọkunrin ni ó bí tabi ọmọbinrin.

8 “Bí kò bá ní agbára láti mú aguntan wa, kí ó mú àdàbà meji tabi ọmọ ẹyẹlé meji, ọ̀kan fún ẹbọ sísun, ekeji fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, alufaa yóo ṣe ètùtù fún un, yóo sì di mímọ́.”

Categories
LEFITIKU

LEFITIKU 13

Àwọn Òfin tí ó Jẹmọ́ Àrùn Ara

1 OLUWA sọ fún Mose ati Aaroni pé,

2 “Nígbà tí ibìkan bá lé lára eniyan, tabi tí ara eniyan bá wú tí ọ̀gangan ibẹ̀ sì ń dán, tí ó bá jọ ẹ̀tẹ̀ ní ara rẹ̀, kí wọ́n mú olúwarẹ̀ tọ Aaroni, alufaa wá; tabi kí wọ́n mú un wá sí ọ̀dọ̀ ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Aaroni, tí ó jẹ́ alufaa.

3 Kí alufaa náà yẹ ọ̀gangan ibi tí àrùn náà wà lára ẹni náà wò. Bí irun ọ̀gangan ibẹ̀ bá di funfun, tí àrùn náà bá jẹ wọ inú ara ẹni náà lọ, tí ó jìn ju awọ ara rẹ̀ lọ, àrùn ẹ̀tẹ̀ ni. Nígbà tí alufaa bá yẹ̀ ẹ́ wò, kí ó pè é ní aláìmọ́.

4 Ṣugbọn bí ọ̀gangan ibẹ̀ bá funfun tí kò sì jìn ju awọ ara rẹ̀ lọ, tí irun ọ̀gangan ibẹ̀ kò sì di funfun, kí alufaa ti abirùn náà mọ́lé fún ọjọ́ meje.

5 Ní ọjọ́ keje, alufaa náà yóo yẹ abirùn náà wò, bí àrùn náà kò bá tàn káàkiri ara rẹ̀, kí alufaa tún tì í mọ́lé fún ọjọ́ meje sí i.

6 Nígbà tí ó bá tún di ọjọ́ keje, kí alufaa tún yẹ̀ ẹ́ wò. Bí ọ̀gangan ibi tí àrùn náà wà bá bẹ̀rẹ̀ sí wòdú, tí àrùn náà kò sì tàn káàkiri ara rẹ̀, kí alufaa pe ẹni náà ní mímọ́, ara rẹ̀ wú lásán ni; kí ó fọ aṣọ rẹ̀, yóo sì di mímọ́.

7 Ṣugbọn bí ibi tí ó wú náà bá bẹ̀rẹ̀ sí tàn káàkiri ní ara rẹ̀, lẹ́yìn tí ó fi ara rẹ̀ han alufaa fún ìwẹ̀nùmọ́, kí ó tún pada lọ fi ara han alufaa.

8 Kí alufaa tún yẹ̀ ẹ́ wò, bí ibi tí ó wú náà bá tàn káàkiri sí i ní ara rẹ̀, kí alufaa pè é ní aláìmọ́; àrùn ẹ̀tẹ̀ ni.

9 “Nígbà tí àrùn ẹ̀tẹ̀ bá mú ẹnìkan, kí wọ́n mú olúwarẹ̀ tọ alufaa lọ.

10 Kí alufaa yẹ̀ ẹ́ wò, bí ibìkan bá wú ní ara rẹ̀, tí ó funfun, tí ó sì sọ irun ọ̀gangan ibẹ̀ di funfun, bí ibi tí ó wú yìí bá di egbò,

11 a jẹ́ pé àrùn ẹ̀tẹ̀ gan-an ni ó wà ní ara ẹni náà. Kí alufaa pè é ní aláìmọ́; kí ó má wulẹ̀ tì í mọ́lé, nítorí pé aláìmọ́ ni.

12 Bí àrùn ẹ̀tẹ̀ bá bo gbogbo ara eniyan láti orí dé àtẹ́lẹsẹ̀ níwọ̀n bí alufaa ti lérò pé ó lè mọ lára eniyan,

13 nígbà náà kí alufaa yẹ olúwarẹ̀ wò, bí àrùn ẹ̀tẹ̀ yìí bá ti bo gbogbo ara rẹ̀ patapata, kí ó pè é ní mímọ́. Bí gbogbo ara rẹ̀ patapata bá ti di funfun, ó di mímọ́.

14 Ṣugbọn gbàrà tí egbò kan bá ti hàn lára rẹ̀, ó di aláìmọ́.

15 Kí alufaa yẹ ojú egbò náà wò, kí ó sì pe abirùn náà ní aláìmọ́, irú egbò yìí jẹ́ aláìmọ́ nítorí pé ẹ̀tẹ̀ ni.

16 Ṣugbọn tí egbò yìí bá jiná, tí ojú rẹ̀ pada di funfun, kí ẹni náà pada tọ alufaa lọ.

17 Kí alufaa yẹ̀ ẹ́ wò, bí ojú egbò náà bá ti funfun, nígbà náà ni kí alufaa tó pe abirùn náà ní mímọ́, ó ti di mímọ́.

18 “Bí oówo bá sọ eniyan lára, tí oówo náà sì san.

19 Bí ọ̀gangan ibẹ̀ bá wú, tí ó funfun tabi tí ó pọ́n, kí olúwarẹ̀ lọ fihan alufaa.

20 Kí alufaa yẹ̀ ẹ́ wò, bí wúwú tí ó wú yìí bá jìn ju awọ ara rẹ̀ lọ, tí irun rẹ̀ bá sì funfun; kí alufaa pè é ní aláìmọ́; àrùn ẹ̀tẹ̀ ni, ẹ̀tẹ̀ ni ó jẹ jáde gẹ́gẹ́ bí oówo.

21 Ṣugbọn bí alufaa bá yẹ̀ ẹ́ wò, tí irun ọ̀gangan ibẹ̀ kò sì di funfun, tí wúwú tí ó wú kò sì jìn ju awọ ara olúwarẹ̀ lọ, ṣugbọn tí ó wòdú, kí alufaa ti ẹni náà mọ́lé fún ọjọ́ meje.

22 Bí àrùn yìí bá bẹ̀rẹ̀ sí tàn káàkiri lára olúwarẹ̀, kí alufaa pè é ní aláìmọ́; àrùn ẹ̀tẹ̀ ni.

23 Ṣugbọn bí àmì yìí kò bá paradà níbi tí ó wà, tí kò sì tàn káàkiri, àpá oówo lásán ni, kí alufaa pe ẹni náà ní mímọ́.

24 “Tabi bí iná bá jó eniyan lára, tí ó sì di egbò, tí ọ̀gangan ibẹ̀ bá pọ́n tabi tí ó funfun,

25 kí alufaa yẹ̀ ẹ́ wò. Bí irun ọ̀gangan ibẹ̀ bá funfun, tí ó sì jìn ju awọ ara rẹ̀ lọ, àrùn ẹ̀tẹ̀ ni; ẹ̀tẹ̀ ni ó jẹ jáde níbi tí iná ti jó olúwarẹ̀. Kí alufaa pè é ní aláìmọ́; àrùn ẹ̀tẹ̀ ni.

26 Ṣugbọn bí alufaa bá yẹ̀ ẹ́ wò, tí irun ọ̀gangan ibẹ̀ kò funfun, tí kò sì jìn ju awọ ara rẹ̀ lọ, ṣugbọn tí ó wòdú, kí alufaa ti ẹni náà mọ́lé fún ọjọ́ meje.

27 Ní ọjọ́ keje kí alufaa yẹ̀ ẹ́ wò, tí àrùn náà bá ti bẹ̀rẹ̀ sí tàn káàkiri ara rẹ̀, kí alufaa pe ẹni náà ní aláìmọ́; àrùn ẹ̀tẹ̀ ni.

28 Bí ibi tí ó wú yìí bá wà bí ó ṣe wà, tí kò sì tàn káàkiri, ṣugbọn tí ó wòdú; àpá iná lásán ni, kí alufaa pè é ní mímọ́.

29 “Bí ọkunrin tabi obinrin bá ní àrùn kan ní orí tabi ní irùngbọ̀n,

30 kí alufaa yẹ̀ ẹ́ wò, bí ó bá jìn wọnú ju awọ ara lọ, tí irun ọ̀gangan ibẹ̀ bá pọ́n, tí ó sì fẹ́lẹ́, kí alufaa pè é ní aláìmọ́; àrùn ẹ̀yi ni, tíí ṣe àrùn ẹ̀tẹ̀ irun orí tabi ti irùngbọ̀n.

31 Bí alufaa bá yẹ àrùn ẹ̀yi yìí wò, tí kò bá jìn ju awọ ara lọ, tí irun dúdú kò sì hù jáde ninu rẹ̀, kí alufaa ti ẹni náà mọ́lé fún ọjọ́ meje.

32 Nígbà tí ó bá di ọjọ́ keje, kí alufaa yẹ ẹni náà wò. Bí ẹ̀yi náà kò bá tàn káàkiri, tí irun ibẹ̀ kò sì pọ́n, tí ẹ̀yi náà kò sì jìn ju awọ ara rẹ̀ lọ,

33 kí ó fá irun orí tabi ti àgbọ̀n olúwarẹ̀, ṣugbọn kí ó má fá irun ọ̀gangan ibi tí ẹ̀yi náà wà. Kí alufaa tún ti ẹni náà mọ́lé fún ọjọ́ meje sí i.

34 Nígbà tí ó bá di ọjọ́ keje, kí alufaa yẹ àrùn ẹ̀yi náà wò, tí àrùn náà kò bá tàn káàkiri sí i, tí kò sì jìn ju awọ ara lọ, kí alufaa pè é ní mímọ́, kí ó fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì di mímọ́.

35 Ṣugbọn bí àrùn ẹ̀yi yìí bá bẹ̀rẹ̀ sí i tàn káàkiri lẹ́yìn ìwẹ̀nùmọ́,

36 kí alufaa tún yẹ̀ ẹ́ wò, bí ẹ̀yi náà bá ti gbilẹ̀ lára rẹ̀, kí alufaa má wulẹ̀ wò bóyá irun rẹ̀ pọ́n tabi kò pọ́n mọ́, aláìmọ́ ni.

37 Ṣugbọn bí ẹ̀yi yìí bá ti dáwọ́ dúró, tí irun dúdú ti bẹ̀rẹ̀ sí hù ní ọ̀gangan ibẹ̀, ẹ̀yi náà ti san, ẹni náà sì ti di mímọ́. Kí alufaa pè é ní mímọ́.

38 “Bí ibìkan lára ọkunrin tabi obinrin bá déédé ṣẹ́ funfun,

39 kí alufaa yẹ̀ ẹ́ wò, bí ọ̀gangan ibẹ̀ bá funfun díẹ̀ tí ó dúdú díẹ̀, ara olúwarẹ̀ kàn fín lásán ni, ó mọ́.

40 “Bí irun orí ọkunrin bá re, orí rẹ̀ pá ni, ṣugbọn ó mọ́.

41 Bí irun orí ẹnìkan bá re, ní gbogbo iwájú títí dé ẹ̀bá etí rẹ̀, orí rẹ̀ pá ni; ó mọ́.

42 Ṣugbọn bí ibi tí ó pá ní orí rẹ̀ tabi iwájú rẹ̀ yìí bá lé, tí ó sì pọ́n, ẹ̀tẹ̀ ni ó fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí jẹ jáde níbi tí orí tabi iwájú rẹ̀ ti pá.

43 Kí alufaa yẹ̀ ẹ́ wò, tí ibi tí àrùn yìí ti wú ní orí tabi iwájú rẹ̀ bá pọ́n, tí ó sì dàbí ẹ̀tẹ̀ lára rẹ̀,

44 adẹ́tẹ̀ ni ọkunrin náà, kò mọ́; alufaa sì gbọdọ̀ pè é ní aláìmọ́. Orí rẹ̀ ni àrùn yìí wà.

45 “Ẹni tí ó ní àrùn ẹ̀tẹ̀ yìí gbọdọ̀ wọ aṣọ tí ó ya, kí ó fi apá kan irun orí rẹ̀ sílẹ̀ játijàti, kí ó bo ètè rẹ̀ òkè, kí ó sì máa ké pé, ‘Aláìmọ́! Aláìmọ́!’

46 Yóo jẹ́ aláìmọ́, níwọ̀n ìgbà tí àrùn yìí bá wà lára rẹ̀. Ó jẹ́ aláìmọ́; òun nìkan ni yóo sì máa dá gbé lẹ́yìn ibùdó.

Àwọn Òfin tí Ó Jẹmọ́ Kí Nǹkan Séèébu

47 “Nígbà tí àrùn ẹ̀tẹ̀ bá wà lára aṣọ kan, kì báà jẹ́ pé òwú tabi irun tí wọ́n fi hun aṣọ náà,

48 tabi lára aṣọkáṣọ, kì báà jẹ́ olówùú tabi onírun, tabi lára awọ, tabi lára ohunkohun tí a fi awọ ṣe.

49 Bí ibi tí àrùn yìí wà bá bẹ̀rẹ̀ sí í pọ́n tabi, kí ó ní àwọ̀ bíi ti ewéko, kì báà jẹ́ aṣọ olówùú, tabi ti onírun, tabi kí ó jẹ́ awọ tabi ohunkohun tí a fi awọ ṣe, àrùn ẹ̀tẹ̀ ni; dandan ni kí wọ́n fihan alufaa.

50 Kí alufaa yẹ àrùn náà wò, kí ó sì ti aṣọ tí àrùn náà ràn mọ́ mọ́lé fún ọjọ́ meje.

51 Kí ó yẹ àrùn ara aṣọ náà wò ní ọjọ́ keje, bí ó bá ti tàn káàkiri lára aṣọ tabi awọ náà, ohun yòówù tí wọ́n lè máa fi aṣọ náà ṣe, irú ẹ̀tẹ̀ tí ó máa ń ràn káàkiri ni; kò mọ́.

52 Kí alufaa jó aṣọ náà, ibi yòówù tí àrùn náà lè wà lára rẹ̀, kì báà jẹ́ aṣọ onírun tabi olówùú, tabi ohunkohun tí wọ́n fi awọ ṣe; nítorí pé irú àrùn tí ó máa ń ràn káàkiri ara ni; jíjó ni kí wọ́n jó o níná.

53 “Bí alufaa bá yẹ̀ ẹ́ wò, tí àrùn náà kò bá ràn káàkiri lára aṣọ náà tabi ohun èlò awọ náà,

54 alufaa yóo pàṣẹ pé kí wọ́n fọ ohun èlò tí àrùn wà lára rẹ̀ yìí, yóo sì tún tì í mọ́lé fún ọjọ́ meje sí i.

55 Alufaa yóo tún yẹ ohun èlò tí àrùn náà ràn mọ́ wò lẹ́yìn tí wọ́n bá ti fọ̀ ọ́. Bí ọ̀gangan ibi tí àrùn yìí ràn mọ́ kò bá mọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò tàn káàkiri sí i; sibẹ kò mọ́; jíjó ni ó níláti jó o níná, kì báà jẹ́ iwájú, tabi ẹ̀yìn aṣọ tabi awọ náà ni àrùn ràn mọ́.

56 Ṣugbọn nígbà tí alufaa bá yẹ̀ ẹ́ wò, tí ó sì rí i pé àrùn náà ti wòdú lẹ́yìn tí a fọ aṣọ náà, kí ó gé ọ̀gangan ibẹ̀ kúrò lára ẹ̀wù, tabi aṣọ, tabi awọ náà.

57 Bí ó bá tún jẹ jáde lára ẹ̀wù, tabi lára aṣọ, tabi ohun èlò aláwọ náà, a jẹ́ pé ó bẹ̀rẹ̀ sí tàn káàkiri nìyí, jíjó ni kí ó jó ohun èlò náà níná.

58 Ṣugbọn ẹ̀wù tabi aṣọ, tabi ohun èlò awọ, tí àrùn yìí bá lọ kúrò lára rẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n ti fọ̀ ọ́, kí olúwarẹ̀ tún un fọ̀ lẹẹkeji, yóo sì di mímọ́.”

59 Ó jẹ́ òfin tí ó jẹmọ́ àrùn ẹ̀tẹ̀ tí ó bá wà lára ẹ̀wù tabi aṣọ, láti fi mọ̀ bóyá ó mọ́ tabi kò mọ́, kì báà jẹ́ aṣọ onírun tabi olówùú, tabi ohun èlò aláwọ.

Categories
LEFITIKU

LEFITIKU 14

Ìwẹ̀nùmọ́ lẹ́yìn Àrùn Ara

1 OLUWA sọ fún Mose pé,

2 “Òfin tí ó jẹmọ́ ti ọjọ́ ìwẹ̀nùmọ́ adẹ́tẹ̀ nìyí: kí wọ́n mú adẹ́tẹ̀ náà wá sí ọ̀dọ̀ alufaa.

3 Kí alufaa jáde kúrò ninu àgọ́, kí ó sì yẹ̀ ẹ́ wò bí àrùn ẹ̀tẹ̀ náà bá ti san.

4 Alufaa yóo pàṣẹ pé kí wọ́n bá ẹni tí wọ́n fẹ́ ṣe ìwẹ̀nùmọ́ fún mú ẹyẹ mímọ́ meji wá ati igi kedari, pẹlu aṣọ pupa tẹ́ẹ́rẹ́ kan, ati ewé hisopu.

5 Alufaa yóo pàṣẹ pé kí wọ́n pa ọ̀kan ninu àwọn ẹyẹ náà sinu ìkòkò amọ̀, lórí odò tí ń ṣàn.

6 Yóo mú ẹyẹ tí ó wà láàyè ati igi kedari, ati aṣọ pupa tẹ́ẹ́rẹ́, ati ewé hisopu, yóo pa wọ́n pọ̀, yóo sì tì wọ́n bọ inú ẹ̀jẹ̀ ẹyẹ tí wọ́n pa lórí odò tí ń ṣàn.

7 Yóo wọ́n ọn sí ara ẹni tí wọ́n fẹ́ wẹ̀ mọ́ kúrò ninu àrùn ẹ̀tẹ̀ náà nígbà meje. Lẹ́yìn náà alufaa yóo pè é ní mímọ́, yóo sì jẹ́ kí ẹyẹ keji tí ó wà láàyè, fò wọ igbó lọ.

8 Kí ẹni tí wọ́n fẹ́ wẹ̀ mọ́ náà fọ aṣọ rẹ̀, kí ó fá irun rẹ̀, kí ó sì wẹ̀, yóo sì di mímọ́. Lẹ́yìn náà, yóo wá sí ibùdó, ṣugbọn ẹ̀yìn àgọ́ rẹ̀ ni yóo máa gbé fún ọjọ́ meje.

9 Ní ọjọ́ keje yóo fá irun orí rẹ̀, ati irùngbọ̀n rẹ̀, ati irun ìpéǹpéjú rẹ̀ ati gbogbo irun ara rẹ̀ patapata, yóo fọ gbogbo aṣọ rẹ̀. Lẹ́yìn náà, yóo wẹ̀, yóo sì di mímọ́.

10 “Ní ọjọ́ kẹjọ, yóo mú ọ̀dọ́ àgbò meji tí kò lábàwọ́n, ati ọ̀dọ́ abo aguntan ọlọ́dún kan tí kò lábàwọ́n, ati ìdámẹ́wàá lọ́nà mẹta ìwọ̀n efa ìyẹ̀fun tí ó kúnná dáradára, tí a fi òróró pò ati ìwọ̀n ìgò òróró kan fún ẹbọ ohun jíjẹ.

11 Alufaa tí ó ṣe ètò ìwẹ̀nùmọ́ ẹni náà yóo mú adẹ́tẹ̀ náà ati àwọn nǹkan ìwẹ̀nùmọ́ wá siwaju OLUWA lẹ́nu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ.

12 Lẹ́yìn náà, yóo mú ọ̀kan ninu àwọn ọ̀dọ́ àgbò náà, yóo fi rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi, pẹlu ìwọ̀n ìgò òróró kan, yóo fì wọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì níwájú OLUWA.

13 Alufaa náà yóo pa àgbò náà níbi tí wọ́n ti máa ń pa ẹran fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ati ti ẹbọ sísun ninu ibi mímọ́, nítorí pé ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi jẹ́ ti alufaa, gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀; ohun mímọ́ patapata ni.

14 Alufaa yóo mú díẹ̀ ninu ẹ̀jẹ̀ ẹran ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi yìí, yóo fi kan ṣóńṣó etí ọ̀tún, ati àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún ati àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún ẹni tí wọ́n fẹ́ wẹ̀ mọ́.

15 Alufaa yóo mú ninu ìwọ̀n ìgò òróró náà, yóo dà á sí àtẹ́lẹwọ́ òsì rẹ̀.

16 Yóo ti ìka ọ̀tún rẹ̀ bọ òróró tí ó wà ní ọwọ́ òsì rẹ̀, yóo sì fi ìka rẹ̀ wọ́n òróró náà níwájú OLUWA ní ìgbà meje.

17 Alufaa yóo mú ninu òróró tí ó kù ní ọwọ́ òsì rẹ̀, yóo fi kan ṣóńṣó etí ọ̀tún ẹni tí wọ́n fẹ́ sọ di mímọ́, ati àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, ati àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún rẹ̀, tí ó ti kọ́ fi ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi kàn.

18 Alufaa yóo fi òróró tí ó kù ní ọwọ́ rẹ̀ ra orí ẹni tí wọ́n fẹ́ sọ di mímọ́. Lẹ́yìn náà, yóo ṣe ètùtù fún un níwájú OLUWA.

19 “Alufaa yóo rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ láti ṣe ètùtù fún ẹni tí wọ́n fẹ́ sọ di mímọ́, lẹ́yìn náà, yóo pa ẹran ẹbọ sísun náà.

20 Alufaa yóo rú ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ lórí pẹpẹ. Bẹ́ẹ̀ ni alufaa yóo ṣe ṣe ètùtù fún un, tí yóo sì di mímọ́.

21 “Ṣugbọn bí adẹ́tẹ̀ náà bá talaka tóbẹ́ẹ̀ tí apá rẹ̀ kò ká àwọn nǹkan tí a kà sílẹ̀ wọnyi, ó lè mú àgbò kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi, tí alufaa yóo fì, láti fi ṣe ètùtù fún un. Kí ó sì tún mú ìdámẹ́wàá ìwọ̀n efa ìyẹ̀fun kan tí ó kúnná dáradára, tí wọ́n fi òróró pò fún ẹbọ ohun jíjẹ, pẹlu ìwọ̀n ìgò òróró kan,

22 ati àdàbà meji tabi ọmọ ẹyẹlé meji, èyíkéyìí tí apá rẹ̀ bá ká. Wọn yóo fi ọ̀kan rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, wọn yóo sì fi ekeji rú ẹbọ sísun.

23 Ní ọjọ́ kẹjọ, yóo kó wọn tọ alufaa wá ní ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ, níwájú OLUWA fún ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀.

24 Alufaa yóo mú àgbò ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi ati ìwọ̀n ìgò òróró náà, yóo fì wọ́n bí ẹbọ fífì níwájú OLUWA.

25 Yóo pa àgbò ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi, yóo sì mú díẹ̀ ninu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, yóo fi kan ṣóńṣó etí ọ̀tún ẹni tí wọ́n fẹ́ sọ di mímọ́ ati àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, ati àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún rẹ̀.

26 Alufaa yóo bu díẹ̀ ninu òróró náà sí àtẹ́lẹwọ́ òsì rẹ̀,

27 yóo ti ìka bọ inú òróró tí ó wà ní ọwọ́ òsì yìí, yóo sì wọ́n ọn sílẹ̀ níwájú OLUWA nígbà meje.

28 Alufaa yóo mú díẹ̀ ninu òróró tí ó wà ni ọwọ́ òsì rẹ̀, yóo fi kan ṣóńṣó etí ọ̀tún ẹni tí wọ́n fẹ́ sọ di mímọ́ ati àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, ati àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún rẹ̀ tí ó ti kọ́ fi ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi kàn.

29 Alufaa yóo mú òróró tí ó kù ní ọwọ́ rẹ̀ yóo sì fi ra orí ẹni tí wọ́n fẹ́ wẹ̀ mọ́, láti fi ṣe ètùtù fún un níwájú OLUWA.

30 Yóo fi èyí tí apá rẹ̀ bá ká rúbọ: yálà àdàbà tabi ẹyẹlé;

31 ọ̀kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ekeji fún ẹbọ sísun, pẹlu ẹbọ ohun jíjẹ. Alufaa yóo sì ṣe ètùtù fún un níwájú OLUWA.

32 Èyí ni òfin tí ó jẹmọ́ ti ẹni tí ó ní àrùn ẹ̀tẹ̀, ṣugbọn tí apá rẹ̀ kò ká àwọn ohun ìrúbọ fún ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀.”

Bí Ara Ògiri Bá Séèébu

33 OLUWA sọ fún Mose ati Aaroni pé,

34 “Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ Kenaani tí n óo fun yín, tí yóo jẹ́ ohun ìní yín, bí mo bá fi àrùn ẹ̀tẹ̀ sí ilé kan ninu ilẹ̀ yín.

35 Ẹni tí ó ni ilé náà yóo wá sọ fún alufaa pé, ‘Ó dàbí ẹni pé àrùn kan wà ní ilé mi.’

36 Kí alufaa pàṣẹ pé kí wọn kó gbogbo ohun tí ó wà ninu ilé náà jáde, kí ó tó lọ yẹ àrùn náà wò; kí ó má baà pe gbogbo ohun tí ó wà ninu ilé náà ní aláìmọ́; lẹ́yìn náà, kí alufaa lọ wo ilé náà.

37 Kí ó yẹ àrùn náà wò, bí ó bá jẹ́ pé lára ògiri ilé ni àrùn yìí wà, tí ibi tí ó wà lára ògiri náà dàbí àwọ̀ ewéko tabi tí ó pọ́n, tí ọ̀gangan ibẹ̀ sì jìn ju ara ògiri lọ.

38 Kí alufaa jáde kúrò ninu ilé náà, kí ó lọ síbi ìlẹ̀kùn, kí ó ti ìlẹ̀kùn ilé náà fún ọjọ́ meje.

39 Alufaa yóo pada wá ní ọjọ́ keje láti yẹ ilé náà wò. Bí àrùn bá ti tàn káàkiri lára ògiri ilé náà,

40 yóo pàṣẹ pé kí wọn yọ àwọn òkúta tí àrùn wà lára wọn, kí wọ́n kó wọn sí ibìkan tí kò mọ́ lẹ́yìn ìlú.

41 Yóo pàṣẹ pé kí wọ́n ha gbogbo ògiri ilé náà yípo, kí wọ́n kó gbogbo ohun tí wọ́n fi rẹ́ ilé, tí wọ́n ha kúrò, kí wọ́n dà á sí ibìkan tí kò mọ́ lẹ́yìn ìlú.

42 Wọn yóo wá wá àwọn òkúta mìíràn, wọn yóo fi dípò àwọn tí wọ́n yọ kúrò, yóo sì fi ohun ìrẹ́lé mìíràn tún ilé náà rẹ́.

43 “Bí àrùn yìí bá tún jẹ jáde lára ilé náà, lẹ́yìn tí ó ti yọ àwọn òkúta àkọ́kọ́ jáde, tí ó ti ha ògiri ilé náà, tí ó sì ti tún un rẹ́,

44 alufaa yóo lọ yẹ ilé náà wò. Bí àrùn náà bá tàn káàkiri lára ògiri ilé náà, a jẹ́ pé àrùn ẹ̀tẹ̀ tí í máa ń tàn káàkiri ni; ilé náà kò mọ́.

45 Wọ́n gbọdọ̀ wó o lulẹ̀ ni, kí wọ́n ru gbogbo òkúta rẹ̀ ati igi tí wọ́n fi kọ́ ọ ati ohun ìrẹ́lé tí wọ́n fi rẹ́ ẹ jáde kúrò láàrin ìlú, lọ sí ibi tí kò mọ́.

46 Ẹnikẹ́ni tí ó bá wọ ilé náà lẹ́yìn tí alufaa ti tì í pa, yóo di aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.

47 Ẹnikẹ́ni tí ó bá sùn ninu ilé náà tabi tí ó bá jẹun ninu rẹ̀ gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀.

48 “Ṣugbọn bí alufaa bá wá yẹ ilé náà wò, tí àrùn náà kò bá tàn káàkiri lára ògiri rẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n ti tún un rẹ́, alufaa yóo pe ilé náà ní mímọ́, nítorí àrùn náà ti san.

49 Nígbà tí alufaa bá fẹ́ sọ ilé náà di mímọ́, yóo mú ẹyẹ kéékèèké meji ati igi kedari ati aṣọ pupa tẹ́ẹ́rẹ́ kan, ati ewé hisopu,

50 yóo pa ọ̀kan ninu àwọn ẹyẹ náà sinu ìkòkò amọ̀ lórí odò tí ń ṣàn,

51 yóo mú igi Kedari ati ewé hisopu ati aṣọ pupa tẹ́ẹ́rẹ́ náà, ati ẹyẹ keji, tí ó wà láàyè, yóo tì wọ́n bọ inú ẹ̀jẹ̀ ẹyẹ tí ó pa lórí odò tí ń ṣàn, yóo wọ́n ọn sára ilé náà nígbà meje.

52 Bẹ́ẹ̀ ni yóo ṣe fi ẹ̀jẹ̀ ẹyẹ náà ati omi tí ń ṣàn, ati ẹyẹ tí ó wà láàyè, ati igi Kedari, ati ewé hisopu, ati aṣọ pupa tẹ́ẹ́rẹ́ náà sọ ilé náà di mímọ́ pada.

53 Yóo ju ẹyẹ náà sílẹ̀ kí ó lè fò jáde kúrò ninu ìlú, lọ sinu pápá, yóo fi ṣe ètùtù fún ìwẹ̀nùmọ́ ilé náà, ilé náà yóo sì di mímọ́.”

54 Àwọn òfin tí a ti kà sílẹ̀ wọnyi ni òfin tí ó jẹmọ́ oríṣìíríṣìí àrùn ẹ̀tẹ̀ ati ti ẹ̀yi ara;

55 ati ti àrùn ẹ̀tẹ̀ lára aṣọ tabi lára ilé,

56 ati ti oríṣìíríṣìí egbò, ati oówo, ati ti ara wúwú, tabi ti aṣọ tabi ilé tí àrùn ẹ̀tẹ̀ bò,

57 láti fi hàn bí ó bá jẹ́ mímọ́, tabi kò jẹ́ mímọ́. Àwọn ni òfin tí ó jẹmọ́ àrùn ẹ̀tẹ̀.

Categories
LEFITIKU

LEFITIKU 15

Àwọn Ohun Àìmọ́ tí Ń Jáde Lára

1 OLUWA ní kí Mose ati Aaroni

2 sọ fún àwọn eniyan Israẹli pé, “Nígbà tí nǹkan bá dà jáde lára ọkunrin, nǹkan tí ó jáde lára rẹ̀ yìí jẹ́ aláìmọ́.

3 Èyí sì ni òfin tí ó jẹmọ́ àìmọ́ rẹ̀, nítorí nǹkan tí ó ti ara rẹ̀ jáde; kì báà jẹ́ pé ó ń dà lọ́wọ́ lọ́wọ́, tabi ó ti dà tán, nǹkan tí ó dà yìí jẹ́ àìmọ́ lára rẹ̀.

4 Ibùsùn tí ẹni náà bá dùbúlẹ̀ lé lórí di aláìmọ́, ohunkohun tí ó bá sì fi jókòó di aláìmọ́ pẹlu.

5 Kí ẹnikẹ́ni tí ó bá fara kan ibùsùn rẹ̀ fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀, yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.

6 Ẹnikẹ́ni tí ó bá jókòó lórí ohunkohun tí ẹni tí nǹkan bá dà lára rẹ̀ bá fi jókòó, kí ó fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀; yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.

7 Ẹnikẹ́ni tí ó bá fara kan ẹni náà, kí ó fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀, yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.

8 Bí ẹnikẹ́ni tí nǹkan dà lára rẹ̀ bá tutọ́ sí ara ẹni tí ó mọ́, kí ẹni náà fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀, yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.

9 Gàárì ẹṣin tí ẹni tí nǹkan bá dà lára rẹ̀ bá fi gun ẹṣin di aláìmọ́.

10 Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì fi ọwọ́ kan ohunkohun, ninu ohun tí ó fi jókòó di aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́. Kí ẹnikẹ́ni tí ó bá ru èyíkéyìí ninu àwọn nǹkan tí ẹni náà fi jókòó, fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀; olúwarẹ̀ yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.

11 Ẹni tí nǹkan ọkunrin dà lára rẹ̀ yìí gbọdọ̀ fọ ọwọ́ rẹ̀, ẹnikẹ́ni tí ẹni náà bá fi ọwọ́ kàn, kí ó tó fọ ọwọ́ rẹ̀, olúwarẹ̀ gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀ yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.

12 Kí wọ́n fọ́ kòkò tí ẹni tí nǹkan dà lára rẹ̀ yìí bá fi ọwọ́ kàn. Bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ohun èlò onígi tí ó bá fọwọ́ kàn, wọ́n gbọdọ̀ fọ̀ wọn.

13 “Nígbà tí wọ́n bá sọ ẹni tí nǹkan dà lára rẹ̀ yìí di mímọ́ kúrò ninu ohun tí ó dà lára rẹ̀, kí ó ka ọjọ́ meje fún ìwẹ̀nùmọ́, kí ó fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀ ninu odò tí ó ń ṣàn; yóo sì di mímọ́.

14 Nígbà tí ó bá di ọjọ́ kẹjọ, kí ó mú àdàbà meji, tabi ọmọ ẹyẹlé meji, kí ó wá siwaju OLUWA lẹ́nu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ, kí ó sì kó wọn fún alufaa.

15 Alufaa yóo fi wọ́n rúbọ: yóo fi ọ̀kan rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, yóo sì fi ekeji rú ẹbọ sísun. Yóo ṣe ètùtù fún ìwẹ̀nùmọ́ ọkunrin náà, níwájú OLUWA.

16 “Kí ọkunrin tí nǹkan ọkunrin rẹ̀ bá dà sí lára, kí ó wẹ gbogbo ara rẹ̀ láti òkè dé ilẹ̀, yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.

17 Gbogbo aṣọ ati awọ tí nǹkan ọkunrin náà bá dà sí gbọdọ̀ jẹ́ fífọ̀, kí ó sì jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.

18 Bí ọkunrin bá bá obinrin lòpọ̀, tí nǹkan ọkunrin sì jáde lára rẹ̀, kí àwọn mejeeji wẹ̀, kí wọ́n sì jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.

19 “Nígbà tí obinrin bá ń ṣe nǹkan oṣù rẹ̀, kí ó wà ní ipò àìmọ́ fún ọjọ́ meje. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì fi ara kàn án jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.

20 Ohunkohun tí ó bá dùbúlẹ̀ lé lórí, tabi tí ó jókòó lé lórí ní gbogbo àkókò àìmọ́ rẹ̀ yóo di aláìmọ́.

21 Kí ẹnikẹ́ni tí ó bá fara kan ibùsùn rẹ̀, fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀; yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.

22 Kí ẹnikẹ́ni tí ó bá fara kan ohunkohun tí ó fi jókòó, fọ aṣọ rẹ̀, kí ó wẹ̀; yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.

23 Kì báà jẹ́ ibùsùn rẹ̀ ni, tabi ohunkohun tí ó fi jókòó ni eniyan bá fi ara kàn, ẹni náà yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.

24 Bí ọkunrin kan bá bá a lòpọ̀ nígbà tí ó bá ń ṣe nǹkan oṣù rẹ̀, ọkunrin náà yóo jẹ́ aláìmọ́ fún ọjọ́ meje, ibùsùn tí ọkunrin náà bá sì dùbúlẹ̀ lé lórí yóo jẹ́ aláìmọ́.

25 “Bí ẹ̀jẹ̀ bá ń dà lára obinrin fún ọpọlọpọ ọjọ́, tí kì í sì í ṣe àkókò nǹkan oṣù rẹ̀, tabi tí nǹkan oṣù rẹ̀ bá dà kọjá iye ọjọ́ tí ó yẹ kí ó dà, ó jẹ́ aláìmọ́ ní gbogbo àkókò tí ẹ̀jẹ̀ ń dà lára rẹ̀. Yóo jẹ́ aláìmọ́ bí ìgbà tí ó ń ṣe nǹkan oṣù rẹ̀.

26 Ibùsùn tí ó bá dùbúlẹ̀ lé lórí, ní gbogbo ọjọ́ tí nǹkan yìí bá fi ń dà lára rẹ̀ yóo jẹ́ aláìmọ́; ohunkohun tí ó bá sì fi jókòó di aláìmọ́ gẹ́gẹ́ bíi ti àkókò tí ó ń ṣe nǹkan oṣù rẹ̀.

27 Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì fi ara kan ibùsùn tabi ìjókòó rẹ̀, yóo di aláìmọ́; kí ó fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀, yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.

28 Ṣugbọn nígbà tí ẹ̀jẹ̀ náà bá dá, kí ó ka ọjọ́ meje lẹ́yìn ọjọ́ náà; lẹ́yìn náà, ó di mímọ́.

29 Nígbà tí ó bá di ọjọ́ kẹjọ, kí ó mú àdàbà meji, tabi ọmọ ẹyẹlé meji tọ alufaa lọ ní ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ.

30 Kí alufaa fi ọ̀kan rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, kí ó sì fi ekeji rú ẹbọ sísun, kí ó ṣe ètùtù fún un níwájú OLUWA nítorí ohun àìmọ́ tí ó jáde lára rẹ̀.

31 “Bẹ́ẹ̀ ni o óo ṣe ya àwọn eniyan Israẹli kúrò lára àìmọ́ wọn, kí wọ́n má baà sọ ibi mímọ́ tí ó wà láàrin wọn di aláìmọ́, kí wọ́n sì kú.”

32 Òfin yìí ni ó jẹmọ́ ti ọkunrin tí nǹkankan tabi nǹkan ọkunrin bá dà lára rẹ̀, tí ó sì ti ipa bẹ́ẹ̀ di aláìmọ́;

33 ati obinrin tí ó ṣe nǹkan oṣù rẹ̀ tabi tí nǹkan oṣù di àìsàn sí lára; ẹnikẹ́ni tí nǹkan bá sá ti ń dà lára rẹ̀, kì báà jẹ́ ọkunrin tabi obinrin, ati ọkunrin tí ó bá bá obinrin tí ó jẹ́ aláìmọ́ lòpọ̀.

Categories
LEFITIKU

LEFITIKU 16

Ọjọ́ Ètùtù

1 Lẹ́yìn tí meji ninu àwọn ọmọ Aaroni kú, nígbà tí wọ́n fi iná tí kò mọ́ rúbọ sí OLUWA, OLUWA bá sọ fún Mose pé,

2 “Sọ fún Aaroni arakunrin rẹ pé kí ó má ṣe máa wọ ibi mímọ́ jùlọ, tí ó wà lẹ́yìn aṣọ títa, níwájú ìtẹ́ àánú tí ó wà lórí àpótí ẹ̀rí nígbà gbogbo, kí ó má baà kú; nítorí pé n óo fi ara hàn ninu ìkùukùu, lórí ìtẹ́ àánú.

3 Ṣugbọn ohun tí yóo ṣe, nígbà tí yóo bá wọ ibi mímọ́ náà nìyí: kí ó mú ọ̀dọ́ akọ mààlúù kan lọ́wọ́ fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ati àgbò kan fún ẹbọ sísun.

4 “Kí ó kọ́kọ́ wẹ̀, lẹ́yìn náà, kí ó wọ àwọn aṣọ mímọ́ nnì: ẹ̀wù funfun mímọ́, pẹlu ṣòkòtò funfun, kí ó fi ọ̀já funfun di àmùrè, kí ó sì dé fìlà funfun.

5 “Yóo gba òbúkọ meji lọ́wọ́ ìjọ eniyan Israẹli fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ati àgbò kan fún ẹbọ sísun.

6 Aaroni yóo fi ọ̀dọ́ mààlúù kan rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ fún ara rẹ̀, yóo sì ṣe ètùtù fún ara rẹ̀ ati ilé rẹ̀.

7 Lẹ́yìn náà yóo mú àwọn ewúrẹ́ mejeeji, yóo fà wọ́n kalẹ̀ níwájú OLUWA, ní ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ.

8 Lẹ́yìn náà, yóo ṣẹ́ gègé lórí àwọn ewúrẹ́ mejeeji, gègé kan fún OLUWA, ekeji fún Asaseli.

9 Aaroni yóo fa ẹran tí gègé OLUWA bá mú kalẹ̀ níwájú OLUWA, yóo sì fi rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀.

10 Ṣugbọn láàyè ni yóo fa ẹran tí gègé Asaseli bá mú kalẹ̀ níwájú OLUWA, yóo ṣe ètùtù lórí rẹ̀, yóo sì tú u sílẹ̀, kí ó sá tọ Asaseli lọ ninu aṣálẹ̀.

11 “Aaroni yóo fa akọ mààlúù kan kalẹ̀ tí yóo fi rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ fún ara rẹ̀, yóo sì ṣe ètùtù fún ara rẹ̀ ati ilé rẹ̀; yóo pa akọ mààlúù náà fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ fún ara rẹ̀.

12 Lẹ́yìn náà, yóo mú ẹ̀yinná láti orí pẹpẹ tí ó wà níwájú OLUWA sinu àwo turari, yóo sì bu turari olóòórùn dídùn tí wọ́n gún, ẹ̀kúnwọ́ meji, yóo sì gbé e lọ sinu ibi tí aṣọ ìbòjú wà.

13 Yóo da turari náà sórí iná níwájú OLUWA, kí èéfín turari náà lè bo ìtẹ́ àánú tí ó wà lórí àpótí ẹ̀rí, kí Aaroni má baà kú.

14 Yóo mú díẹ̀ ninu ẹ̀jẹ̀ akọ mààlúù náà, yóo fi ìka wọ́n ọn siwaju ìbòrí ìtẹ́ àánú. Bákan náà, yóo fi ìka wọ́n ẹ̀jẹ̀ náà siwaju Àpótí Ẹ̀rí nígbà meje.

15 “Lẹ́yìn náà yóo pa ewúrẹ́ ìrúbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ tí ó jẹ́ ti àwọn eniyan Israẹli, yóo sì gbé ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ lọ sinu ibi tí aṣọ ìbòjú wà, yóo sì ṣe é bí ó ti ṣe ẹ̀jẹ̀ akọ mààlúù, yóo wọ́n ọn siwaju ìbòrí ìtẹ́ àánú, yóo sì tún wọ́n ọn siwaju Àpótí Ẹ̀rí.

16 Bẹ́ẹ̀ ni yóo ti ṣe ètùtù fún ibi mímọ́ náà, nítorí àìmọ́ àwọn eniyan Israẹli, ati nítorí ìrékọjá ati gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wọn, bẹ́ẹ̀ gan-an ni yóo sì ṣe sí Àgọ́ Àjọ tí ó wà láàrin wọn, nítorí àìmọ́ wọn.

17 Kò ní sí ẹnikẹ́ni ninu Àgọ́ Àjọ nígbà tí ó bá wọlé lọ láti ṣe ètùtù ninu ibi mímọ́ náà, títí tí yóo fi jáde, lẹ́yìn tí ó bá ti ṣe ètùtù fún ara rẹ̀, ati ilé rẹ̀, ati fún gbogbo ìjọ eniyan Israẹli.

18 Lẹ́yìn náà, yóo jáde lọ sí ibi pẹpẹ tí ó wà níwájú OLUWA, yóo sì ṣe ètùtù fún un. Yóo mú díẹ̀ ninu ẹ̀jẹ̀ akọ mààlúù náà ati ti ewúrẹ́ náà, yóo sì fi ra àwọn ìwo pẹpẹ náà yípo.

19 Yóo sì fi ìka wọ́n díẹ̀ ninu ẹ̀jẹ̀ náà sí ara pẹpẹ nígbà meje, yóo sọ ọ́ di mímọ́, yóo sì yà á sí mímọ́ kúrò ninu àìmọ́ àwọn eniyan Israẹli.

Ewúrẹ́ tí A Di Ẹrù Ẹ̀ṣẹ̀ lé Lórí

20 “Lẹ́yìn ìgbà tí ó bá ti parí ṣíṣe ètùtù fún ibi mímọ́ náà, ati fún Àgọ́ Àjọ náà, ati pẹpẹ náà, yóo fa ààyè ewúrẹ́ náà kalẹ̀.

21 Yóo gbé ọwọ́ rẹ̀ mejeeji lé e lórí, yóo jẹ́wọ́ gbogbo àìṣedéédé ati ìrékọjá ati ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli lórí rẹ̀, yóo sì kó wọn lé e lórí, yóo fà á lé ẹnìkan tí ó ti múra sílẹ̀ lọ́wọ́, láti fà á lọ sinu aṣálẹ̀.

22 Òbúkọ náà yóo sì fi orí rẹ̀ ru gbogbo àìṣedéédé wọn, títí tí ẹni náà yóo fi fà á dé ibi tí eniyan kì í gbé, ibẹ̀ ni yóo ti sọ ọ́ sílẹ̀ kí ó lè wọ inú aṣálẹ̀ lọ.

23 “Aaroni yóo pada wá sinu Àgọ́ Àjọ, yóo bọ́ àwọn aṣọ funfun tí ó wọ̀ kí ó tó wọ inú ibi mímọ́ lọ, yóo sì fi wọ́n sílẹ̀ níbẹ̀.

24 Yóo wẹ̀ ní ibi mímọ́, yóo kó àwọn aṣọ tirẹ̀ wọ̀, yóo sì jáde. Lẹ́yìn náà yóo rú ẹbọ sísun tirẹ̀ ati ẹbọ sísun ti àwọn eniyan náà, yóo sì ṣe ètùtù fún ara rẹ̀ ati fún àwọn eniyan náà.

25 Yóo sun ọ̀rá ẹran ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ lórí pẹpẹ náà.

26 Ẹni tí ó fa ewúrẹ́ náà tọ Asaseli lọ ninu aṣálẹ̀ yóo fọ aṣọ rẹ̀, yóo sì wẹ̀, lẹ́yìn náà, ó lè wọ ibùdó.

27 Lẹ́yìn náà, wọn yóo gbé òkú akọ mààlúù ati ti òbúkọ tí wọ́n fi rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ati ẹ̀jẹ̀ wọn tí wọ́n gbé wọ ibi mímọ́ lọ láti fi ṣe ètùtù, wọn yóo rù wọ́n jáde kúrò ní ibùdó, wọn yóo sì dáná sun ati awọ, ati ara ẹran ati nǹkan inú wọn.

28 Ẹni tí ó bá lọ sun wọ́n, yóo fọ aṣọ rẹ̀, yóo sì wẹ̀, lẹ́yìn náà, ó lè wọ ibùdó wá.

Ìlànà fún Ìrántí Ọjọ́ Ètùtù

29 “Kí ó jẹ́ ìlànà fun yín títí lae pé, ní ọjọ́ kẹwaa oṣù keje, ati onílé ati àlejò yín, ẹ gbọdọ̀ gbààwẹ̀, ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan.

30 Nítorí pé, ní ọjọ́ náà ni wọn yóo máa ṣe ètùtù fun yín, tí yóo sọ yín di mímọ́ kúrò ninu gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ yín, kí ẹ lè jẹ́ mímọ́ níwájú OLUWA.

31 Ọjọ́ ìsinmi tí ó lọ́wọ̀ ni ó jẹ́ fun yín, ẹ sì gbọdọ̀ gbààwẹ̀; ìlànà ni èyí jẹ́ fun yín títí lae.

32 Alufaa tí wọ́n bá ta òróró sí lórí, tí wọ́n sì yà sí mímọ́ gẹ́gẹ́ bí alufaa àgbà ní ipò baba rẹ̀ ni kí ó máa ṣe ètùtù, kí ó sì máa wọ aṣọ mímọ́ náà.

33 Yóo ṣe ètùtù fún Àgọ́ mímọ́ náà, ati Àgọ́ Àjọ, ati pẹpẹ náà, kí ó sì ṣe ètùtù fún àwọn alufaa pẹlu ati ìjọ eniyan náà.

34 Èyí yóo jẹ́ ìlànà ayérayé fun yín, kí wọ́n lè máa ṣe ètùtù fún àwọn ọmọ Israẹli ní ẹ̀ẹ̀kan lọ́dún, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn.”

Mose sì ṣe gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí OLUWA pa fún un.

Categories
LEFITIKU

LEFITIKU 17

Ẹ̀jẹ̀ Lọ́wọ̀–Ninu Rẹ̀ Ni Ẹ̀mí wà

1 OLUWA sọ fún Mose pé

2 kí ó sọ fún Aaroni, ati àwọn ọmọkunrin rẹ̀, ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli pé, “Ohun tí OLUWA paláṣẹ nìyí:

3 Bí ẹnìkan ninu àwọn ọmọ Israẹli bá pa akọ mààlúù, tabi ọ̀dọ́ aguntan, tabi ewúrẹ́ kan ní ibùdó, tabi lẹ́yìn ibùdó,

4 tí kò bá mú un wá sí ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ láti fi ṣe ẹ̀bùn fún OLUWA níwájú Àgọ́ mímọ́ rẹ̀, olúwarẹ̀ yóo jẹ̀bi ìtàjẹ̀sílẹ̀, ó ti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀, a óo sì yọ ọ́ kúrò láàrin àwọn eniyan rẹ̀.

5 OLUWA pa àṣẹ yìí kí àwọn ọmọ Israẹli lè máa mú ẹran ìrúbọ tí wọ́n bá pa ninu pápá wá fún OLUWA, kí wọn mú un tọ alufaa wá lẹ́nu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ, kí wọn sì pa á láti fi rú ẹbọ alaafia sí OLUWA.

6 Alufaa yóo sì máa wọ́n ẹ̀jẹ̀ wọn sí ara pẹpẹ OLUWA lẹ́nu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ, yóo sì sun ọ̀rá wọn bí ẹbọ sísun olóòórùn dídùn sí OLUWA.

7 Kí àwọn ọmọ Israẹli má baà tún máa fi ẹran wọn rúbọ sí oriṣa bí wọ́n ti ń ṣe rí. Òfin yìí wà fún arọmọdọmọ wọn títí lae.

8 “Bákan náà, ẹnikẹ́ni ninu àwọn ọmọ Israẹli tabi àlejò tí ń ṣe àtìpó láàrin wọn, tí ó bá rú ẹbọ sísun tabi ẹbọ mìíràn,

9 tí kò bá mú ẹran tí yóo fi rú ẹbọ náà wá sí ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ láti fi rúbọ sí OLUWA, a óo yọ ẹni náà kúrò láàrin àwọn eniyan rẹ̀.

10 “Bí ẹnikẹ́ni ninu àwọn ọmọ Israẹli tabi àlejò tí ń ṣe àtìpó láàrin wọn bá jẹ ẹ̀jẹ̀, èmi OLUWA yóo bínú sí olúwarẹ̀, n óo sì yọ ọ́ kúrò láàrin àwọn eniyan rẹ̀.

11 Nítorí pé, ninu ẹ̀jẹ̀ ni ẹ̀mí ohun alààyè gbogbo wà; mo sì ti fun yín, pé kí ẹ máa ta á sórí pẹpẹ, kí ẹ máa fi ṣe ètùtù fún ẹ̀mí yín; nítorí pé ẹ̀jẹ̀ níí ṣe ètùtù, nítorí ẹ̀mí tí ó wà ninu rẹ̀.

12 Nítorí rẹ̀ ni mo fi sọ fún ẹ̀yin ọmọ Israẹli pé, ẹnikẹ́ni ninu yín kò gbọdọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni àlejò tí ń ṣe àtìpó láàrin yín kò gbọdọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀.

13 “Ẹnikẹ́ni ninu àwọn ọmọ Israẹli, tabi àwọn àlejò tí ń ṣe àtìpó láàrin wọn tí ó bá lọ ṣe ọdẹ tí ó sì pa ẹran tabi ẹyẹ tí eniyan lè jẹ, ó níláti ro gbogbo ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sílẹ̀ kí ó sì wa erùpẹ̀ bò ó.

14 Nítorí pé, ninu ẹ̀jẹ̀ ni ẹ̀mí gbogbo ohun alààyè wà, nítorí náà ni mo fi sọ fún ẹ̀yin ọmọ Israẹli pé, ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀ ẹ̀dá alààyè kankan, nítorí pé, ninu ẹ̀jẹ̀ ni ẹ̀mí ẹ̀dá alààyè gbogbo wà, ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ ẹ́, a óo yọ ọ́ kúrò.

15 “Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì jẹ ohunkohun tí ó kú fúnra rẹ̀, tabi tí ẹranko burúkú fà ya, kí ẹni náà fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀, yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́, lẹ́yìn ìgbà náà ni yóo tó pada di mímọ́.

16 Ṣugbọn, tí kò bá fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀, yóo jìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.”