Orin Arò
1 OLUWA ní kí n sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn nítorí àwọn olórí Israẹli,
2 kí n sọ pé:
Abo kinniun pataki ni ìyá rẹ láàrin àwọn kinniun!
Ó dùbúlẹ̀ láàrin àwọn ọ̀dọ́ kinniun,
ó ń tọ́jú àwọn ọmọ rẹ̀.
3 Ó tọ́ ọ̀kan ninu àwọn ọmọ rẹ̀ dàgbà;
ó di ọ̀dọ́ kinniun.
Ó kọ́ ọ bí wọ́n tí ń ṣe ọdẹ,
ó sì ń pa eniyan jẹ.
4 Àwọn eniyan ayé gbọ́ nípa rẹ̀,
wọ́n tàn án sinu kòtò wọn.
Wọ́n fi ìwọ̀ kọ́ ọ nímú,
wọ́n sì fà á lọ sí ilẹ̀ Ijipti.
5 Nígbà tí abo kinniun náà rí i pé ọwọ́ tẹ ọmọ òun,
ati pé igbẹkẹle òun ti dòfo,
ó mú òmíràn ninu àwọn ọmọ rẹ̀,
ó tọ́ ọ di ọ̀dọ́ kinniun.
6 Ó ń yan kiri láàrin àwọn kinniun;
nítorí ó ti di ọ̀dọ́ kinniun tí ó lágbára,
ó kọ́ bí wọn tí ń ṣe ọdẹ,
ó sì ń pa eniyan jẹ.
7 Ó wó ilé ìṣọ́ wọn lulẹ̀;
ó sọ ìlú wọn di ahoro.
Ẹ̀rù ba gbogbo Ilẹ̀ náà, ati gbogbo àwọn tí ń gbé ibẹ̀,
nígbà tí wọ́n gbọ́ bíbú rẹ̀.
8 Àwọn orílẹ̀-èdè bá dójú lé e,
wọ́n dẹ tàkúté fún un ní gbogbo ọ̀nà,
wọ́n da àwọ̀n wọn bò ó,
wọ́n sì mú un ninu kòtò tí wọn gbẹ́ fún un.
9 Wọ́n sọ ìwọ̀ sí i nímú,
wọ́n gbé e jù sinu àhámọ́,
wọ́n sì fà á lọ sí ọ̀dọ̀ ọba Babiloni.
Wọ́n fi sí àtìmọ́lé,
kí wọ́n má baà gbọ́ ohùn rẹ̀ mọ́ lórí àwọn òkè Israẹli.
10 Ìyá rẹ dàbí àjàrà inú ọgbà
tí a gbìn sí ẹ̀gbẹ́ odò;
ó rúwé, ó yọ ẹ̀ka,
nítorí ó rí omi lọpọlọpọ.
11 Ẹ̀ka rẹ̀ tí ó lágbára
ni a fi gbẹ́ ọ̀pá àṣẹ fún àwọn olórí.
Ó dàgbà, ó ga fíofío, láàrin àwọn igi igbó.
Ó rí i bí ó ti ga, tí ẹ̀ka rẹ̀ sì pọ̀.
12 Ṣugbọn a fa àjàrà náà tu pẹlu ibinu,
a sì jù ú sílẹ̀.
Afẹ́fẹ́ ìlà oòrùn mú kí ó gbẹ,
gbogbo èso rẹ̀ sì rẹ̀ dànù.
Igi rẹ̀ tí ó lágbára gbẹ, iná sì jó o.
13 Nisinsinyii, a ti tún un gbìn sinu aṣálẹ̀,
ninu ilẹ̀ gbígbẹ níbi tí kò sí omi.
14 Iná ṣẹ́ lára igi rẹ̀,
ó sì jó gbogbo ẹ̀ka ati èso rẹ̀.
Kò sì ní igi tí ó lágbára mọ́,
tí a lè fi gbẹ́ ọ̀pá àṣẹ fún ọba.
Dájúdájú ọ̀rọ̀ arò ni ọ̀rọ̀ yìí, ó sì ti di orin arò.