Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 1

Ayọ̀ Tòótọ́

1 Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni náà

tí kò gba ìmọ̀ràn àwọn eniyan burúkú,

tí kò bá àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ rìn,

tí kò sì bá àwọn ẹlẹ́gàn kẹ́gbẹ́.

2 Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ní ìfẹ́ sí òfin OLUWA,

a sì máa ṣe àṣàrò lórí rẹ̀ tọ̀sán-tòru.

3 Yóo dàbí igi tí a gbìn sí etí odò

tí ń so ní àkókò tí ó yẹ,

tí ewé rẹ̀ kì í rẹ̀.

Gbogbo ohun tí ó bá dáwọ́lé níí máa yọrí sí rere.

4 Àwọn eniyan burúkú kò rí bẹ́ẹ̀,

ṣugbọn wọ́n dàbí fùlùfúlù tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ lọ.

5 Nítorí náà àwọn eniyan burúkú kò ní rí ìdáláre,

bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ kò ní le wà ní àwùjọ àwọn olódodo.

6 Nítorí OLUWA ń dáàbò bo àwọn olódodo,

ṣugbọn àwọn eniyan burúkú yóo ṣègbé.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *