Adura ìrànlọ́wọ́ lówùúrọ̀
1 OLUWA, àwọn ọ̀tá mi pọ̀ pupọ!
Ọ̀pọ̀ ni ó ń dìde sí mi!
2 Ọpọlọpọ ni àwọn tí ń sọ kiri pé,
Ọlọrun kò ní gbà mí sílẹ̀!
3 Ṣugbọn ìwọ OLUWA ni ààbò mi,
ògo mi, ati ẹni tí ó fún mi ní ìgboyà.
4 Mo ké pe OLUWA,
ó sì dá mi lóhùn láti òkè mímọ́ rẹ̀ wá.
5 Mo dùbúlẹ̀, mo sùn, mo sì jí,
nítorí OLUWA ni ó ń gbé mi ró.
6 Ẹgbẹẹgbẹrun ọ̀tá tó yí mi ká
kò le bà mí lẹ́rù.
7 Dìde, OLUWA, gbà mí, Ọlọrun mi!
Nítorí ìwọ ni o lu gbogbo àwọn ọ̀tá mi bolẹ̀,
tí o sì ṣẹgun àwọn eniyan burúkú.
8 OLUWA níí gbani,
kí ibukun rẹ̀ kí ó wà lórí àwọn eniyan rẹ̀.