Ògo Ọlọrun ninu àwọn ohun tí Ó dá
1 Ojú ọ̀run ń sọ̀rọ̀ ògo Ọlọrun,
òfuurufú sì ń kéde iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.
2 Ọjọ́ dé ọjọ́ ń sọ ọ́ ní àsọgbà
òru dé òru sì ń fi ìmọ̀ rẹ̀ hàn.
3 Wọn kò fọ èdè kankan, wọn kò sì sọ ọ̀rọ̀;
bẹ́ẹ̀ ni a kò gbọ́ ohùn wọn;
4 sibẹ ìró wọn la gbogbo ayé já,
ọ̀rọ̀ wọn sì dé òpin ayé.
Ó pàgọ́ fún oòrùn lójú ọ̀run,
5 tí ó ń yọ jáde bí ọkọ iyawo tí ń jáde láti inú yàrá rẹ̀,
ati bí akọni tí ara ń wá láti fi tayọ̀tayọ̀ sáré ìje.
6 Láti apá kan ojú ọ̀run ni ó ti ń yọ wá,
a máa yípo gbogbo ojú ọ̀run dé apá keji;
kò sì sí ohun tí ó bọ́ lọ́wọ́ ooru rẹ̀.
Òfin OLUWA
7 Òfin OLUWA pé, a máa sọ ọkàn jí;
àṣẹ OLUWA dájú, ó ń sọ òpè di ọlọ́gbọ́n.
8 Ìlànà OLUWA tọ́, ó ń mú ọkàn yọ̀,
àṣẹ OLUWA péye, a máa lani lójú.
9 Ìbẹ̀rù OLUWA pé, ó wà títí lae,
ìdájọ́ OLUWA tọ́, òdodo ni gbogbo wọn.
10 Wọ́n wuni ju wúrà lọ,
àní ju ojúlówó wúrà lọ;
wọ́n sì dùn ju oyin,
àní, wọ́n dùn ju oyin tí ń kán láti inú afárá lọ.
11 Pẹlupẹlu àwọn ni wọ́n ń ki èmi iranṣẹ rẹ, nílọ̀,
èrè pupọ sì ń bẹ ninu pípa wọ́n mọ́.
12 Ṣugbọn ta ni lè mọ àṣìṣe ara rẹ̀?
Wẹ̀ mí mọ́ ninu àṣìṣe àìmọ̀ mi.
13 Pa èmi iranṣẹ rẹ mọ́ kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀ àmọ̀-ọ́n-mọ̀-dá;
má jẹ́ kí wọ́n jọba lórí mi.
Nígbà náà ni ara mi yóo mọ́,
n kò sì ní jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ ńlá.
14 Jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ẹnu mi, ati àṣàrò ọkàn mi
jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà ní ojú rẹ,
OLUWA ibi ààbò mi ati olùràpadà mi.