Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 20

Adura Ìṣẹ́gun

1 OLUWA óo dá ọ lóhùn ní ọjọ́ ìpọ́njú,

orúkọ Ọlọrun Jakọbu óo dáàbò bò ọ́.

2 Yóo rán olùrànlọ́wọ́ sí ọ láti ilé mímọ́ rẹ̀ wá,

yóo sì tì ọ́ lẹ́yìn láti Sioni wá.

3 Yóo ranti gbogbo ẹbọ ọrẹ rẹ,

yóo sì gba ẹbọ sísun rẹ.

4 Yóo fún ọ ní ohun tí o fẹ́ ninu ọkàn rẹ,

yóo sì mú gbogbo èrò rẹ ṣẹ.

5 Ìhó ayọ̀ ni a óo hó nígbà tí o bá ṣẹgun,

ní orúkọ Ọlọrun wa ni a óo sì fi ọ̀págun wa sọlẹ̀;

OLUWA yóo dáhùn gbogbo ìbéèrè rẹ.

6 Mo wá mọ̀ nisinsinyii pé OLUWA yóo ran ẹni àmì òróró rẹ̀ lọ́wọ́;

OLUWA yóo dá a lóhùn láti ọ̀run mímọ́ rẹ̀ wá

yóo sì fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ fún un ní ìṣẹ́gun ńlá.

7 Àwọn mìíràn gbẹ́kẹ̀lé kẹ̀kẹ́ ogun,

àwọn mìíràn gbẹ́kẹ̀lé ẹṣin,

ṣugbọn ní tiwa, àwa gbẹ́kẹ̀lé orúkọ OLUWA Ọlọrun wa.

8 Àwọn óo kọsẹ̀, wọn óo sì ṣubú,

ṣugbọn àwa óo dìde, a óo sì dúró ṣinṣin.

9 Fún ọba ní ìṣẹ́gun, OLUWA;

kí o sì dá wa lóhùn nígbà tí a bá ń ké pè ọ́.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *