Ọba Atóbijù
1 OLUWA ló ni ilẹ̀ ati gbogbo ohun tí ó wà
ninu rẹ̀,
òun ló ni ayé, ati gbogbo àwọn tí
ń gbé inú rẹ̀;
2 nítorí pé òun ló fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀ lórí òkun,
ó sì gbé e kalẹ̀ lórí ìṣàn omi.
3 Ta ló lè gun orí òkè OLUWA lọ?
Ta ló sì lè dúró ninu ibi mímọ́ rẹ̀?
4 Ẹni tí ọwọ́ rẹ̀ mọ́, tí inú rẹ̀ sì funfun,
tí kò gbẹ́kẹ̀lé oriṣa lásánlàsàn,
tí kò sì búra èké.
5 Òun ni yóo rí ibukun gbà lọ́dọ̀ OLUWA,
tí yóo sì rí ìdáláre gbà lọ́wọ́ Ọlọrun, Olùgbàlà rẹ̀.
6 Irú wọn ni àwọn tí ń wá OLUWA,
àní àwọn tí ń wá ojurere Ọlọrun Jakọbu.
7 Ẹ ṣí sílẹ̀ gbayau, ẹ̀yin ìlẹ̀kùn,
ẹ wà ní ṣíṣí sílẹ̀, ẹ̀yin ìlẹ̀kùn ayérayé,
kí Ọba ògo lè wọlé.
8 Ta ni Ọba ògo yìí?
OLUWA tí ó ní ipá tí ó sì lágbára,
OLUWA tí ó lágbára lógun.
9 Ẹ ṣí sílẹ̀ gbayau, ẹ̀yin ìlẹ̀kùn,
ẹ wà ní ṣíṣí sílẹ̀, ẹ̀yin ìlẹ̀kùn ayérayé,
kí Ọba ògo lè wọlé.
10 Ta ni Ọba ògo yìí?
OLUWA àwọn ọmọ ogun,
òun ni Ọba ògo náà.