Adura Ìrànlọ́wọ́
1 Ìwọ ni mo kígbe pè, OLUWA,
ìwọ ni ààbò mi, má di etí sí mi.
Nítorí bí o bá dákẹ́ sí mi
n óo dàbí àwọn òkú, tí wọ́n ti lọ sinu kòtò.
2 Gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ mi,
bí mo ti ń kígbe sí ọ pé kí o ràn mí lọ́wọ́;
tí mo gbé ọwọ́ mi sókè
sí ìhà ilé mímọ́ rẹ.
3 Má ṣe kó mi lọ pẹlu àwọn eniyan burúkú,
pẹlu àwọn tí ń ṣe iṣẹ́ ibi,
àwọn tí ń bá àwọn aládùúgbò wọn
sọ ọ̀rọ̀ alaafia,
ṣugbọn tí ètekéte ń bẹ ninu ọkàn wọn.
4 San án fún wọn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ wọn,
àní gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ burúkú wọn;
san án fún wọn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ wọn,
fún wọn ní èrè tí ó tọ́ sí wọn.
5 Nítorí pé wọn kò ka iṣẹ́ OLUWA sí,
wọn kò sì bìkítà fún iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀,
OLUWA yóo sọ wọ́n di ilẹ̀,
kò sì ní gbé wọn dìde mọ́.
6 Ẹni ìyìn ni OLUWA!
Nítorí pé ó ti gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ mi.
7 OLUWA ni agbára ati asà mi,
òun ni mo gbẹ́kẹ̀lé;
ó ràn mí lọ́wọ́, ọkàn mi sì kún fún ayọ̀;
mo sì fi orin ìyìn dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀.
8 OLUWA ni agbára àwọn eniyan rẹ̀;
òun ni ààbò ìgbàlà fún ẹni àmì òróró rẹ̀.
9 Gba àwọn eniyan rẹ là, OLUWA,
kí o sì bukun ilẹ̀ ìní rẹ.
Jẹ́ olùṣọ́-aguntan wọn,
kí o sì máa tọ́jú wọn títí lae.