Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 30

Adura Ọpẹ́

1 N óo yìn ọ́, OLUWA,

nítorí pé o ti yọ mí jáde;

o kò sì jẹ́ kí àwọn ọ̀tá mi ó yọ̀ mí.

2 OLUWA, Ọlọrun mi, mo ké pè ọ́,

o sì wò mí sàn.

3 OLUWA, o ti yọ mí kúrò ninu isà òkú

o sọ mí di ààyè láàrin àwọn tí

wọ́n ti wọ inú kòtò.

4 Ẹ kọ orin ìyìn sí OLUWA, ẹ̀yin olùfọkànsìn rẹ̀,

kí ẹ sì fi ọpẹ́ fún orúkọ mímọ́ rẹ̀.

5 Nítorí pé fún ìgbà díẹ̀ ni ibinu rẹ̀,

ṣugbọn títí ayé ni ojurere rẹ̀;

eniyan lè máa sọkún títí di alẹ́,

ṣugbọn ayọ̀ ń bọ̀ fún un lówùúrọ̀.

6 Nígbà tí ara rọ̀ mí,

mo wí ninu ọkàn mi pé,

kò sí ohun tí ó lè mì mí laelae.

7 Nípa ojurere rẹ, OLUWA,

o ti fi ìdí mi múlẹ̀ bí òkè ńlá;

ṣugbọn nígbà tí o fi ojú pamọ́ fún mi,

ìdààmú dé bá mi.

8 Ìwọ ni mò ń ké pè, OLUWA,

OLUWA, ìwọ ni mò ń bẹ̀.

9 Anfaani wo ló wà ninu pé kí n kú?

Èrè wo ló wà ninu pé kí n wọ inú kòtò?

Ṣé erùpẹ̀ lè yìn ọ́?

Ṣé ó lè sọ nípa òdodo rẹ?

10 Gbọ́ OLUWA, kí o sì ṣàánú mi,

OLUWA, ràn mí lọ́wọ́.

11 O ti bá mi sọ ọ̀fọ̀ mi di ijó,

o ti bọ́ aṣọ ọ̀fọ̀ kúrò lára mi,

o sì ti dì mí ní àmùrè ayọ̀,

12 kí ọkàn mi lè máa yìn ọ́ láìdákẹ́.

OLUWA Ọlọrun mi, n óo máa fi ọpẹ́ fún ọ títí lae.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *