Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 32

Ìjẹ́wọ́ Ẹ̀ṣẹ̀

1 Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí a dárí ìrékọjá rẹ̀ jì,

tí a bo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀.

2 Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí OLUWA kò ka ẹ̀ṣẹ̀ sí lọ́rùn,

tí ẹ̀tàn kò sì sí ninu ọkàn rẹ̀.

3 Nígbà tí n kò jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi,

ó rẹ̀ mí wá láti inú,

nítorí kíkérora tí mò ń kérora ní gbogbo ìgbà.

4 Nítorí tọ̀sán-tòru ni o fi ń jẹ mí níyà;

gbogbo agbára mi ló lọ háú,

bí omi tíí gbẹ lákòókò ẹ̀ẹ̀rùn.

5 Mo jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi fún ọ;

n kò sì fi àìdára mi pamọ́ fún ọ.

Mo ní, “Èmi óo jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi fún Oluwa,”

o sì dáríjì mí.

6 Nítorí náà, kí gbogbo olódodo máa gbadura sí ọ;

ní àkókò tí ìpọ́njú bá ń yí lura wọn bí ìṣàn omi ńlá,

kò ní dé ọ̀dọ̀ wọn.

7 Ìwọ ni ibi ìsásí mi;

o pa mí mọ́ kúrò ninu ìṣòro;

o sì fi ìgbàlà yí mi ká.

8 N óo kọ́ ọ, n óo sì tọ́ ọ sí ọ̀nà tí o óo rìn;

n óo máa gbà ọ́ ní ìmọ̀ràn;

n óo sì máa mójútó ọ.

9 Má ṣe dàbí ẹṣin tabi ìbaaka,

tí kò ni ọgbọ́n ninu,

tí a gbọdọ̀ kó ìjánu sí lẹ́nu

kí ó tó lè gbọ́ ti oluwa rẹ̀.

10 Ìrora pọ̀ fún àwọn eniyan burúkú,

ṣugbọn ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ ni ó yí àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé OLUWA ká.

11 Ẹ máa yọ̀ ninu OLUWA;

ẹ fò fún ayọ̀, ẹ̀yin olódodo;

kí ẹ sì hó fún ayọ̀, gbogbo ẹ̀yin ọlọ́kàn mímọ́.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *