Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 33

Orin Ìyìn

1 Ẹ máa yọ̀ ninu OLUWA, ẹ̀yin olódodo!

Yíyin OLUWA ni ó yẹ ẹ̀yin olóòótọ́.

2 Ẹ fi gòjé yin OLUWA,

ẹ fi hapu olókùn mẹ́wàá kọ orin sí i.

3 Ẹ kọ orin titun sí i,

ẹ fi ohun èlò ìkọrin olókùn dárà,

kí ẹ sì hó ìhó ayọ̀.

4 Nítorí ọ̀rọ̀ OLUWA dúró ṣinṣin;

òtítọ́ sì ni ó fi ń ṣe gbogbo iṣẹ́ rẹ̀.

5 OLUWA fẹ́ràn òdodo ati ẹ̀tọ́;

ayé kún fún ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀.

6 Ọ̀rọ̀ ni OLUWA fi dá ojú ọ̀run,

èémí ẹnu rẹ̀ ni ó sì fi dá oòrùn, òṣùpá, ati àwọn ìràwọ̀.

7 Ó wọ́ gbogbo omi òkun jọ bí òkìtì;

ó pa gbogbo omi inú àwọn ibú pọ̀ bí ẹni pé ó rọ ọ́ sinu àgbá ńlá.

8 Kí gbogbo ayé bẹ̀rù OLUWA,

kí gbogbo aráyé dúró níwájú rẹ̀ pẹlu ọ̀wọ̀ ati ìbẹ̀rù!

9 Nítorí pé OLUWA sọ̀rọ̀, ayé wà;

ó pàṣẹ, ayé sì dúró.

10 OLUWA sọ ìmọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè di asán;

ó sì mú kí ètò àwọn eniyan já sófo.

11 Ètò OLUWA wà títí lae,

èrò ọkàn rẹ̀ sì wà láti ìran dé ìran.

12 Ayọ̀ ń bẹ fún orílẹ̀-èdè tí OLUWA jẹ́ Ọlọrun wọn,

àní àwọn eniyan tí ó yàn gẹ́gẹ́ bí ìní rẹ̀!

13 OLUWA bojúwo ilẹ̀ láti ọ̀run,

ó rí gbogbo eniyan;

14 láti orí ìtẹ́ rẹ̀ tí ó gúnwà sí,

ó wo gbogbo aráyé.

15 Òun ni ó dá ọkàn gbogbo wọn,

tí ó sì ń mójútó gbogbo ìṣe wọn.

16 Kì í ṣe pípọ̀ tí àwọn ọmọ ogun pọ̀ ní ń gba ọba là;

kì í sì í ṣe ọ̀pọ̀ agbára níí gba jagunjagun là.

17 Asán ni igbẹkẹle agbára ẹṣin ogun;

kìí ṣe agbára tí ẹṣin ní, ló lè gbani là.

18 Wò ó! OLUWA ń ṣọ́ àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,

àní àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀,

19 kí ó lè gba ọkàn wọn lọ́wọ́ ikú,

kí ó sì mú wọn wà láàyè lákòókò ìyàn.

20 Ọkàn wa ní ìrètí lọ́dọ̀ OLUWA;

òun ni olùrànlọ́wọ́ ati ààbò wa.

21 A láyọ̀ ninu rẹ̀,

nítorí pé a gbẹ́kẹ̀lé orúkọ mímọ́ rẹ̀.

22 OLUWA, jẹ́ kí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ wà lórí wa

bí a ti gbẹ́kẹ̀lé ọ.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *