Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 56

Adura Igbẹkẹle Ọlọrun

1 Ṣàánú mi, Ọlọrun, nítorí pé àwọn eniyan ń lépa mi;

ọ̀tá gbógun tì mí tọ̀sán-tòru.

2 Àwọn ọ̀tá ń lépa mi tọ̀sán-tòru,

ọpọlọpọ ní ń bá mi jà tìgbéraga-tìgbéraga.

3 Nígbà tí ẹ̀rù bá ń bà mí,

èmi yóo gbẹ́kẹ̀lé ọ.

4 Ọlọrun, mo yìn ọ́ fún ọ̀rọ̀ rẹ,

ìwọ ni mo gbẹ́kẹ̀lé láìbẹ̀rù;

kí ni eniyan ẹlẹ́ran ara lè fi mí ṣe?

5 Tọ̀sán-tòru ni wọ́n ń da ọ̀rọ̀ mi rú;

ibi ni gbogbo èrò tí wọn ń gbà sí mi.

6 Wọ́n kó ara wọn jọ, wọ́n sápamọ́,

wọ́n ń ṣọ́ ìrìn ẹsẹ̀ mi,

bí wọn ṣé ń dọdẹ ẹ̀mí mi.

7 Nítorí náà, san ẹ̀san ẹ̀ṣẹ̀ wọn fún wọn;

ninu ibinu rẹ, Ọlọrun, ré àwọn eniyan yìí lulẹ̀.

8 O sá mọ gbogbo ìdààmú mi;

ati bí omijé mi ti pọ̀ tó,

wọ́n ṣá wà ní àkọsílẹ̀ ninu ìwé rẹ.

9 A óo lé àwọn ọ̀tá mi pada

ní ọjọ́ tí mo bá ké pè ọ́.

Mo mọ̀ dájú pé Ọlọrun ń bẹ fún mi.

10 Ọlọrun, tí mo yin ọ̀rọ̀ rẹ̀,

OLUWA, tí mo yin ọ̀rọ̀ rẹ̀;

11 Ọlọrun ni mo gbẹ́kẹ̀lé láìbẹ̀rù.

Kí ni eniyan ẹlẹ́ran ara lè fi mí ṣe?

12 Èmi óo san ẹ̀jẹ́ mi fún ọ, Ọlọrun;

n óo sì mú ẹbọ ọpẹ́ wá fún ọ.

13 Nítorí pé o ti gba ẹ̀mí mi lọ́wọ́ ikú,

o gbà mí, o kò jẹ́ kí n kọsẹ̀,

kí n lè máa rìn níwájú Ọlọrun

ninu ìmọ́lẹ̀ ìyè.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *