Adura Ìrànlọ́wọ́
1 Ṣàánú mi, Ọlọrun, ṣàánú mi,
nítorí ìwọ ni ààbò mi;
abẹ́ òjìji apá rẹ ni n óo fi ṣe ààbò mi,
títí gbogbo àjálù wọnyi yóo fi kọjá.
2 Mo ké pe Ọlọrun Ọ̀gá Ògo,
Ọlọrun tí ó mú èrò rẹ̀ ṣẹ fún mi.
3 Yóo ranṣẹ láti ọ̀run wá, yóo gbà mí là,
yóo dójú ti àwọn tí ń lépa ẹ̀mí mi.
Ọlọrun yóo fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀
ati òtítọ́ rẹ̀ hàn!
4 Ààrin àwọn kinniun ni mo dùbúlẹ̀ sí,
àwọn tí ń jẹ eniyan ní ìjẹ ìwọ̀ra;
eyín wọn dàbí ọ̀kọ̀ ati ọfà,
ahọ́n wọn sì dàbí idà.
5 Gbé ara rẹ ga, Ọlọrun,
gbé ara rẹ ga ju ọ̀run lọ,
kí ògo rẹ sì tàn ká gbogbo ayé.
6 Wọ́n dẹ àwọ̀n sí ojú ọ̀nà mi;
ìpọ́njú dorí mi kodò.
Wọ́n gbẹ́ kòtò sílẹ̀ dè mí,
ṣugbọn àwọn fúnra wọn ni wọ́n jìn sí i.
7 Ọkàn mi dúró ṣinṣin, Ọlọrun,
ọkàn mi dúró ṣinṣin!
N óo kọrin, n óo sì máa yìn ọ́.
8 Jí, ìwọ ọkàn mi!
Ẹ jí, ẹ̀yin ohun èlò orin, ati hapu,
èmi alára náà yóo jí ní òwúrọ̀ kutukutu.
9 OLUWA, n óo máa fi ọpẹ́ fún ọ láàrin àwọn eniyan;
n óo sì máa kọrin ìyìn sí ọ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè.
10 Nítorí pé ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ tóbi, ó ga ju ọ̀run lọ,
òtítọ́ rẹ sì kan ojú ọ̀run.
11 Gbé ara rẹ ga, Ọlọrun,
gbé ara rẹ ga ju ọ̀run lọ,
kí ògo rẹ sì tàn ká gbogbo ayé.