Adura Àgbàlagbà kan
1 OLUWA, ìwọ ni mo sá di;
má jẹ́ kí ojú ó tì mí laelae!
2 Gbà mí, kí o sì yọ mí nítorí òdodo rẹ;
tẹ́tí sí mi kí o sì gbà mí là!
3 Máa ṣe àpáta ààbò fún mi,
jẹ́ odi alágbára fún mi kí o sì gbà mí,
nítorí ìwọ ni ààbò ati odi mi.
4 Ọlọrun mi, gbà mí lọ́wọ́ àwọn eniyan burúkú,
àwọn alaiṣootọ ati ìkà.
5 Nítorí ìwọ OLUWA, ni ìrètí mi,
OLUWA, Ọlọrun mi, ìwọ ni mo gbẹ́kẹ̀lé láti ìgbà èwe mi.
6 Ìwọ ni mo gbára lé láti inú oyún;
ìwọ ni o mú mi jáde láti inú ìyá mi.
Ìwọ ni n óo máa yìn nígbà gbogbo.
7 Mo di ẹni àmúpòwe fún ọpọlọpọ eniyan,
ṣugbọn ìwọ ni ààbò mi tí ó lágbára.
8 Ẹnu mi kún fún ìyìn rẹ,
ó kún fún ògo rẹ tọ̀sán-tòru.
9 Má ta mí nù ní ìgbà ogbó mi;
má sì gbàgbé mi nígbà tí n kò bá lágbára mọ́.
10 Nítorí pé àwọn ọ̀tá mi ń sọ̀rọ̀ mi,
àwọn tí ń lépa ẹ̀mí mi ti pàmọ̀ pọ̀,
11 wọ́n ní, “Ọlọrun ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀;
ẹ lé e, ẹ mú un;
nítorí kò sí ẹni tí yóo gbà á sílẹ̀ mọ́.”
12 Ọlọrun, má jìnnà sí mi;
yára, Ọlọrun mi, ràn mí lọ́wọ́!
13 Jẹ́ kí ojú ó ti àwọn alátakò mi, kí wọn parun;
kí ẹ̀gàn ati ìtìjú bo àwọn tí ń wá ìpalára mi.
14 Ní tèmi, èmi ó máa ní ìrètí nígbà gbogbo,
n óo sì túbọ̀ máa yìn ọ́.
15 N óo máa ṣírò iṣẹ́ rere rẹ,
n óo máa ròyìn iṣẹ́ ìgbàlà rẹ tọ̀sán-tòru,
nítorí wọ́n pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí n kò lè mọ iye wọn.
16 N óo wá ninu agbára OLUWA Ọlọrun,
n óo máa kéde iṣẹ́ òdodo rẹ, àní, iṣẹ́ òdodo tìrẹ nìkan.
17 Ọlọrun, láti ìgbà èwe mi ni o ti kọ́ mi,
títí di òní ni mo sì ń polongo iṣẹ́ ìyanu rẹ,
18 Nisinsinyii tí mo ti dàgbà, tí ewú sì ti gba orí mi,
Ọlọrun, má kọ̀ mí sílẹ̀,
títí tí n óo fi ròyìn iṣẹ́ ńlá rẹ,
àní, iṣẹ́ agbára rẹ, fún gbogbo àwọn ìran tí ń bọ̀.
19 Ọlọrun, iṣẹ́ òdodo rẹ kan ojú ọ̀run,
ìwọ tí o ṣe nǹkan ńlá,
Ọlọrun, ta ni ó dàbí rẹ?
20 O ti jẹ́ kí n rí ọpọlọpọ ìpọ́njú ńlá,
ṣugbọn óo tún mú ìgbé ayé mi pada bọ̀ sípò;
óo tún ti gbé mi dìde láti inú isà òkú.
21 O óo fi kún ọlá mi,
o óo sì tún tù mí ninu.
22 Èmi náà óo máa fi hapu yìn ọ́,
nítorí òtítọ́ rẹ, Ọlọrun mi;
n óo máa fi ohun èlò orin yìn ọ́,
ìwọ ẹni mímọ́ Israẹli.
23 N óo máa kígbe fún ayọ̀,
nígbà tí mo bá ń kọ orin ìyìn sí ọ;
ẹ̀mí mi tí o ti kó yọ, yóo ké igbe ayọ̀.
24 Ẹnu mi yóo ròyìn iṣẹ́ rẹ tọ̀sán-tòru,
nítorí a ti ṣẹgun àwọn tí ó fẹ́ pa mí lára,
a sì ti dójú tì wọ́n.