Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 73

Ìdájọ́ Òdodo Ọlọrun

1 Nítòótọ́ Ọlọrun ṣeun fún Israẹli,

ó ṣeun fún àwọn tí ọkàn wọn mọ́.

2 Ṣugbọn, ní tèmi, mo fẹ́rẹ̀ yọ̀ ṣubú,

ẹsẹ̀ mi fẹ́rẹ̀ tàsé.

3 Nítorí mò ń ṣe ìlara àwọn onigbeeraga

nígbà tí mo rí ọrọ̀ àwọn eniyan burúkú.

4 Wọn kì í jẹ ìrora kankan,

ara wọn dá pé, ó sì jọ̀lọ̀.

5 Wọn kì í ní wahala bí àwọn ẹlòmíràn;

ìyọnu tíí dé bá àwọn ẹlòmíràn kì í dé ọ̀dọ̀ wọn.

6 Nítorí náà, wọn á kó ìgbéraga bọ ọrùn bí ẹ̀gbà,

wọn á fi ìwà ipá bora bí aṣọ.

7 Wọ́n sanra tóbẹ́ẹ̀ tí ojú wọn yíbò;

èrò òmùgọ̀ sì kún ọkàn wọn ní àkúnwọ́sílẹ̀.

8 Wọ́n ń pẹ̀gàn eniyan, wọ́n ń sọ̀rọ̀ pẹlu ìlara;

wọ́n sì ń fi ìgbéraga halẹ̀.

9 Wọ́n ń fi ẹnu wọn sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọrun;

wọn a sì máa sọ̀rọ̀ ìgbéraga káàkiri ayé.

10 Nítorí náà, àwọn eniyan á yipada, wọn á fara mọ́ wọn,

wọn á máa yìn wọ́n, láìbìkítà fún ibi tí wọn ń ṣe.

11 Wọn á máa wí pé, “Báwo ni Ọlọrun ṣe lè mọ̀?

Ǹjẹ́ Ọ̀gá Ògo tilẹ̀ ní ìmọ̀?”

12 Ẹ wò ó! Ayé àwọn eniyan burúkú nìwọ̀nyí;

ara dẹ̀ wọ́n nígbà gbogbo, ọrọ̀ wọn sì ń pọ̀ sí i.

13 Lásán ni gbogbo aáyan mi láti rí i pé ọkàn mi mọ́,

tí mo sì yọwọ́-yọsẹ̀ ninu ibi.

14 Nítorí pé tọ̀sán-tòru ni mò ń rí ìyọnu;

láràárọ̀ ni à ń jẹ mí níyà.

15 Bí mo bá ní, “N óo sọ̀rọ̀ báyìí,”

n óo kó àwọn ọmọ rẹ ṣìnà.

16 Ṣugbọn nígbà tí mo rò bí nǹkan wọnyi ṣe lè yé mi,

mo rí i pé iṣẹ́ tíí dáni lágara ni.

17 Àfi ìgbà tí mo wọ ibi mímọ́ Ọlọrun lọ,

ni mo tó wá rí òye ìgbẹ̀yìn wọn.

18 Nítòótọ́ ibi tí ń yọ̀ ni ó gbé wọn lé,

ó sì mú kí wọn ṣubú sinu ìparun.

19 Wò ó bí wọn ṣe parun lọ́gán,

tí ìpayà sì gbá wọn lọ patapata.

20 Wọ́n dàbí àlá tíí pòórá nígbà tí eniyan bá ta jí.

OLUWA, nígbà tí o bá jí gìrì, wọn óo pòórá.

21 Nígbà tí ọkàn mí bàjẹ́,

tí ọ̀rọ̀ náà gbóná lára mi,

22 mo hùwà òmùgọ̀, n kò sì lóye,

mo sì dàbí ẹranko lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ.

23 Sibẹsibẹ nígbà gbogbo ni mo wà lọ́dọ̀ rẹ;

o sì di ọwọ́ ọ̀tún mi mú.

24 Ò ń fi ìmọ̀ràn rẹ tọ́ mi sọ́nà;

lẹ́yìn náà, o óo sì gbà mí sinu ògo.

25 Ta ni mo ní lọ́run lẹ́yìn rẹ?

Kò sì sí ohun kan tí ó wù mí láyé yìí bíkòṣe ìwọ.

26 Àárẹ̀ lè mú ara ati ẹ̀mí mi,

ṣugbọn Ọlọrun ni agbára ẹ̀mí mi,

ati ìpín mi títí lae.

27 Ó dájú pé àwọn tí ó jìnnà sí ọ yóo ṣègbé,

o óo sì pa àwọn tí ó bá ṣe alaiṣootọ sí ọ run.

28 Ní tèmi o, ó dára láti súnmọ́ Ọlọrun;

mo ti fi ìwọ OLUWA Ọlọrun ṣe ààbò mi,

kí n lè máa ròyìn gbogbo iṣẹ́ rẹ.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *