Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 75

Ọlọrun Onídàájọ́

1 A dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, Ọlọrun; a dúpẹ́.

À ń kéde orúkọ rẹ,

a sì ń ròyìn iṣẹ́ ribiribi tí o ṣe.

2 OLUWA ní, “Nígbà tí àkókò tí mo yà sọ́tọ̀ bá tó,

n óo ṣe ìdájọ́ pẹlu àìṣojúṣàájú.

3 Nígbà tí ayé bá ń mì síhìn-ín sọ́hùn-ún,

ati gbogbo àwọn tí ń gbé inú rẹ̀;

èmi a mú kí òpó rẹ̀ dúró wámúwámú.

4 Èmi a sọ fún àwọn tí ń fọ́nnu pé, ‘Ẹ yé fọ́nnu’;

èmi a sì sọ fún àwọn eniyan burúkú pé, ‘Ẹ yé ṣe ìgbéraga.’

5 Ẹ má halẹ̀ ju bí ó ti yẹ lọ,

ẹ má sì gbéraga.”

6 Nítorí pé kì í ṣe láti ìlà oòrùn,

tabi láti ìwọ̀ oòrùn,

bẹ́ẹ̀ ni kì í sì í ṣe apá gúsù tabi àríwá ni ìgbéga tií wá.

7 Ọlọrun níí dájọ́ bí ó ti wù ú:

á rẹ ẹnìkan sílẹ̀, á sì gbé ẹlòmíràn ga.

8 Ife kan wà ní ọwọ́ OLUWA,

Ibinu Oluwa ló kún inú rẹ̀,

ó ń ru bí ọtí àní bí ọtí tí a ti lú,

yóo ṣẹ́ ninu rẹ̀;

gbogbo àwọn eniyan burúkú ilẹ̀ ayé ni yóo sì mu ún,

wọn óo mu ún tán patapata tòun ti gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ rẹ̀.

9 Ṣugbọn èmi óo máa yọ̀ títí lae,

n óo kọ orin ìyìn sí Ọlọrun Jakọbu.

10 Ọlọrun yóo gba gbogbo agbára ọwọ́ àwọn eniyan burúkú kúrò;

ṣugbọn yóo fi agbára kún agbára fún àwọn olódodo.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *