Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 76

Ọlọrun Ajàṣẹ́gun

1 Àwọn ará Juda mọ Ọlọrun,

orúkọ rẹ̀ sì lọ́wọ̀ ní Israẹli.

2 Ilé rẹ̀ wà ní Salẹmu,

ibùgbé rẹ̀ wà ní Sioni.

3 Níbẹ̀ ni ó ti ṣẹ́ ọfà ọ̀tá tí ń rọ̀jò,

ati apata, ati idà, ati àwọn ohun ìjà ogun.

4 Ológo ni ọ́, ọlá rẹ sì pọ̀,

ó ju ti àwọn òkè tí ó kún fún ẹran lọ.

5 A gba ìkógun lọ́wọ́ àwọn akikanju,

wọ́n sun oorun àsùn-ùn-jí;

àwọn alágbára kò sì le gbé ọwọ́ láti jà.

6 Nípa ìbáwí rẹ, Ọlọrun Jakọbu,

ati ẹṣin, ati ẹni tó gun ẹṣin,

gbogbo wọn ló ṣubú lulẹ̀, tí wọn kò sì lè mira.

7 Ṣugbọn ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ ni ọ́!

Ta ló tó dúró níwájú rẹ

tí ibinu rẹ bá dé?

8 Láti ọ̀run wá ni o ti ń ṣe ìdájọ́,

ẹ̀rù ba ayé, ayé sì dúró jẹ́ẹ́;

9 nígbà tí Ọlọrun dìde láti gbé ìdájọ́ kalẹ̀,

láti gba gbogbo àwọn tí à ń nilára láyé sílẹ̀.

10 Dájúdájú ibinu eniyan yóo pada di ìyìn fún ọ;

àwọn tí wọ́n bá sì bọ́ lọ́wọ́ ibinu rẹ

yóo ṣe àjọ̀dún rẹ.

11 Jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún OLUWA Ọlọrun rẹ, kí o sì mú un ṣẹ,

kí gbogbo àwọn tí ó yí i ká mú ẹ̀bùn wá

fún ẹni tí ó yẹ kí á bẹ̀rù.

12 Ẹni tí ń gba ẹ̀mí àwọn ìjòyè,

tí ó ń ṣe ẹ̀rù ba àwọn ọba ayé.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *