Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 82

Ọlọrun, Ọba Àwọn Ọba

1 Ọlọrun ti jókòó ní ààyè rẹ̀ ninu ìgbìmọ̀ ọ̀run;

ó sì ń ṣe ìdájọ́ láàrin àwọn ẹ̀dá ọ̀run:

2 “Yóo ti pẹ́ tó tí ẹ̀yin óo máa fi aiṣododo ṣe ìdájọ́,

tí ẹ óo sì máa ṣe ojuṣaaju fún àwọn eniyan burúkú?

3 Ẹ ṣe ìdájọ́ òdodo fún àwọn mẹ̀kúnnù ati àwọn ọmọ aláìníbaba;

ẹ sì máa ṣe ẹ̀tọ́ fún àwọn tí ojú ń pọ́n ati àwọn talaka.

4 Ẹ gba talaka ati aláìní sílẹ̀,

ẹ gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn eniyan burúkú.”

5 Wọn kò ní ìmọ̀ tabi òye,

wọ́n ń rìn kiri ninu òkùnkùn,

títí gbogbo ìpìlẹ̀ ayé fi mì tìtì.

6 Mo ní, “oriṣa ni yín,

gbogbo yín ni ọmọ Ọ̀gá Ògo.

7 Ṣugbọn sibẹsibẹ, ẹ óo kú bí eniyan,

ẹ ó sùn bí èyíkéyìí ninu àwọn ìjòyè.”

8 Dìde, Ọlọrun, ṣe ìdájọ́ ayé,

nítorí tìrẹ ni gbogbo orílẹ̀-èdè!

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *