Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 101

Ìlérí Ọba

1 N óo kọrin ìfẹ́ ati ìdájọ́ òdodo,

OLUWA, ìwọ ni n óo máa kọrin ìyìn sí.

2 N óo múra láti hu ìwà pípé pẹlu ọgbọ́n;

nígbà wo ni o óo wá sọ́dọ̀ mi?

N óo máa fi tọkàntọkàn rin ìrìn pípé ninu ilé mi.

3 N kò ní gba nǹkan burúkú láyè níwájú mi.

Mo kórìíra ìṣe àwọn tí wọ́n tàpá sí Ọlọrun.

N kò sì ní bá wọn lọ́wọ́ sí nǹkankan.

4 Èròkérò yóo jìnnà sí ọkàn mi,

n kò sì ní ṣe ohun ibi kankan,

5 Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń sọ̀rọ̀ ẹnìkejì rẹ̀ níbi,

n óo pa á run,

n kò sì ní gba alágbèéré ati onigbeeraga láàyè.

6 N óo máa fi ojurere wo àwọn olóòótọ́ ní ilẹ̀ náà,

kí wọ́n lè máa bá mi gbé;

ẹni tí ó bá sì ń hu ìwà pípé ni yóo máa sìn mí.

7 Ẹlẹ́tàn kankan kò ní gbé inú ilé mi;

bẹ́ẹ̀ ni òpùrọ́ kankan kò ní dúró níwájú mi.

8 Ojoojumọ ni n óo máa pa àwọn eniyan burúkú run ní ilẹ̀ náà,

n óo lé gbogbo àwọn aṣebi kúrò ninu ìlú OLUWA.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *