Adura Ẹlẹ́ṣẹ̀
1 Ninu ìṣòro ńlá ni mò ń ké pè ọ́, OLUWA!
2 OLUWA, gbóhùn mi,
dẹtí sí ohùn ẹ̀bẹ̀ mi.
3 Bí OLUWA bá ń sàmì ẹ̀ṣẹ̀,
ta ló lè yege?
4 Ṣugbọn ní ìkáwọ́ rẹ ni ìdáríjì wà,
kí á lè máa bẹ̀rù rẹ.
5 Mo gbẹ́kẹ̀lé OLUWA, àní, mo gbé ọkàn mi lé e,
mo sì ní ìrètí ninu ọ̀rọ̀ rẹ̀.
6 Mò ń retí rẹ, OLUWA,
ju bí àwọn aṣọ́de ti máa ń retí kí ilẹ̀ mọ́ lọ,
àní, ju bí àwọn aṣọ́de, ti máa ń retí pé kí ilẹ̀ mọ́.
7 Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ ní ìrètí ninu OLUWA!
Nítorí pé ní ìkáwọ́ rẹ̀ ni ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ wà,
ní ìkáwọ́ rẹ̀ sì ni ìràpadà kíkún wà.
8 Òun óo sì ra Israẹli pada kúrò ninu gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.