Orin Ọpẹ́
1 Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA, nítorí pé ó ṣeun,
nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.
2 Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun tí ó ju gbogbo àwọn oriṣa lọ,
nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.
3 Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA tí ó ju gbogbo àwọn oluwa lọ,
nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.
4 Òun nìkan ṣoṣo ní ń ṣe iṣẹ́ ìyanu ńlá,
nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.
5 Ẹni tí ó fi ọgbọ́n dá ọ̀run,
nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae;
6 ẹni tí ó tẹ́ ilẹ̀ lé orí omi,
nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae;
7 ẹni tí ó dá àwọn ìmọ́lẹ̀ ńlá,
nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.
8 Ó dá oòrùn láti máa ṣe àkóso ọ̀sán,
nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.
9 Ó dá òṣùpá ati ìràwọ̀ láti máa ṣe àkóso òru,
nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.
10 Ẹni tí ó pa àwọn àkọ́bí ní ilẹ̀ Ijipti,
nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae;
11 ó sì kó àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò láàrin wọn,
nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.
12 Pẹlu ipá ati ọwọ́ líle ni ó fi kó wọn jáde,
nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.
13 Ẹni tí ó pín Òkun Pupa sí meji,
nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae;
14 ó sì mú àwọn ọmọ Israẹli kọjá láàrin rẹ̀,
nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae;
15 ṣugbọn ó bi Farao ati àwọn ọmọ ogun
rẹ̀ ṣubú ninu Òkun Pupa,
nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.
16 Ẹni tí ó mú àwọn eniyan rẹ̀ la aṣálẹ̀ já,
nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae;
17 ẹni tí ó pa àwọn ọba ńlá,
nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae;
18 ó sì pa àwọn ọba olókìkí,
nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae;
19 Sihoni ọba àwọn Amori,
nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae;
20 ati Ogu ọba Baṣani,
nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.
21 Ó pín ilẹ̀ wọn fún àwọn eniyan rẹ̀,
nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae;
22 ó fún àwọn ọmọ Israẹli, iranṣẹ rẹ̀,
nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.
23 Òun ni ó ranti wa ní ipò ìrẹ̀lẹ̀ wa,
nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae;
24 ó sì gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa,
nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.
25 Ẹni tí ó pèsè oúnjẹ fún gbogbo ẹ̀dá alààyè,
nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.
26 Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun ọ̀run,