Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 137

Àwọn Ọmọ Israẹli Kọrin Arò ní Ìgbèkùn

1 Lẹ́bàá odò Babiloni ni a jókòó, tí a sọkún,

nígbà tí a ranti Sioni.

2 Lára igi wilo níbẹ̀ ni a fi hapu wa kọ́ sí,

3 nítorí pé níbẹ̀ ni àwọn tí ó kó wa ní ìgbèkùn

ti ní kí á kọrin fún àwọn.

Àwọn tí ó ń pọ́n wa lójú sọ pé kí á dá àwọn lárayá, wọ́n ní,

“Ẹ kọ orin Sioni kan fún wa.”

4 Báwo ni a óo ṣe kọ orin OLUWA ní ilẹ̀ àjèjì?

5 Jerusalẹmu, bí mo bá gbàgbé rẹ,

kí ọwọ́ ọ̀tún mi kí ó rọ.

6 Kí ahọ́n mi lẹ̀ mọ́ èrìgì mi,

bí n kò bá ranti rẹ,

bí n kò bá sì fi Jerusalẹmu ṣe olórí ayọ̀ mi.

7 OLUWA, ranti ohun tí àwọn ará Edomu ṣe

nígbà tí Jerusalẹmu bọ́ sọ́wọ́ ọ̀tá,

tí wọn ń pariwo pé,

“Ẹ wó o palẹ̀! Ẹ wó o palẹ̀! Ẹ wó o títí dé ìpìlẹ̀ rẹ̀.”

8 Babiloni! Ìwọ apanirun!

Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó bá gbẹ̀san lára rẹ,

fún gbogbo ohun tí o ti ṣe sí wa!

9 Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó bá kó àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ rẹ,

tí ó ṣán wọn mọ́ àpáta.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *