Adura Ọpẹ́
1 N óo máa yìn ọ́ tọkàntọkàn OLUWA,
lójú àwọn oriṣa ni n óo máa kọrin ìyìn sí ọ.
2 Ní ìtẹríba, n óo kọjú sí ìhà tẹmpili mímọ́ rẹ,
n óo sì máa yin orúkọ rẹ,
nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ati òtítọ́ rẹ,
nítorí pé o gbé ọ̀rọ̀ rẹ ati orúkọ rẹ ga ju ohunkohun lọ.
3 Ní ọjọ́ tí mo ké pè ọ́, o dá mi lóhùn,
o sì fún mi ní agbára kún agbára.
4 OLUWA, gbogbo ọba ayé ni yóo máa yìn ọ́,
nítorí pé wọ́n ti gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ.
5 Wọn óo sì máa kọrin nípa iṣẹ́ OLUWA,
nítorí pé ògo OLUWA tóbi.
6 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé OLUWA ga lọ́lá,
ó ka àwọn onírẹ̀lẹ̀ sí,
ṣugbọn ó mọ àwọn onigbeeraga lókèèrè.
7 Bí mo tilẹ̀ wà ninu ìpọ́njú,
sibẹ, o dá mi sí;
o dojú ìjà kọ ibinu àwọn ọ̀tá mi,
o sì fi ọwọ́ agbára rẹ gbà mí.
8 OLUWA yóo mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ lórí mi,
OLUWA, ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.
Má kọ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ sílẹ̀.