Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 143

Adura Ìrànlọ́wọ́

1 OLUWA, gbọ́ adura mi;

fetí sí ẹ̀bẹ̀ mi!

Dá mi lóhùn ninu òtítọ́ ati òdodo rẹ.

2 Má dá èmi ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ lẹ́jọ́,

nítorí pé kò sí ẹ̀dá alààyè tí ẹjọ́ rẹ̀ lè tọ́ níwájú rẹ.

3 Ọ̀tá ti lé mi bá,

ó ti lù mí bolẹ̀;

ó jù mí sinu òkùnkùn,

bí ẹni tí ó ti kú tipẹ́tipẹ́.

4 Nítorí náà ọkàn mi rẹ̀wẹ̀sì;

ọkàn mi sì pòrúúruù.

5 Mo ranti ìgbà àtijọ́,

mo ṣe àṣàrò lórí gbogbo ohun tí o ti ṣe,

mo sì ronú lórí àwọn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.

6 Mo na ọwọ́ sí ọ fún ìrànlọ́wọ́;

bí òùngbẹ omi í tií gbẹ ilẹ̀ gbígbẹ,

bẹ́ẹ̀ ni òùngbẹ rẹ ń gbẹ ọkàn mi.

7 OLUWA, yára dá mi lóhùn!

Ẹ̀mí mi ti fẹ́rẹ̀ pin!

Má fara pamọ́ fún mi,

kí n má baà dàbí àwọn tí ó ti lọ sinu isà òkú.

8 Jẹ́ kí n máa ranti ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ láràárọ̀,

nítorí ìwọ ni mo gbẹ́kẹ̀lé.

Kọ́ mi ní ọ̀nà tí n óo máa rìn,

nítorí pé ìwọ ni mo gbójú sókè sí.

9 OLUWA, gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi;

ìwọ ni mo sá di.

10 Kọ́ mi láti máa ṣe ìfẹ́ rẹ,

nítorí pé ìwọ ni Ọlọrun mi.

Jẹ́ kí ẹ̀mí rere rẹ máa tọ́ mi ní ọ̀nà tí ó tọ́.

11 Nítorí ti orúkọ rẹ, OLUWA, dá mi sí;

ninu òtítọ́ rẹ, yọ mí ninu ìpọ́njú.

12 Ninu ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀, pa àwọn ọ̀tá mi,

kí o sì pa gbogbo àwọn tí ń ṣe inúnibíni mi run,

nítorí pé iranṣẹ rẹ ni mí.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *