Categories
ÌWÉ ÒWE

ÌWÉ ÒWE 12

1 Ẹni tí ó fẹ́ ìtọ́sọ́nà, ó fẹ́ ìmọ̀,

ṣugbọn ẹni tí ó kórìíra ìbáwí òmùgọ̀ ni.

2 Eniyan rere a máa ní ojurere lọ́dọ̀ OLUWA,

ṣugbọn ẹni tí ń pète ìkà ni yóo dá lẹ́bi.

3 Kò sí ẹni tí ó lè ti ipa ìwà ìkà fi ìdí múlẹ̀,

ṣugbọn gbòǹgbò olódodo kò ní fà tu.

4 Obinrin oníwàrere ni adé orí ọkọ rẹ̀,

ṣugbọn obinrin tí ń dójúti ọkọ dàbí ọyún inú egungun.

5 Èrò ọkàn olódodo dára,

ṣugbọn ẹ̀tàn ni ìmọ̀ràn àwọn eniyan burúkú.

6 Ọ̀rọ̀ àwọn eniyan burúkú dàbí ẹni tí ó lúgọ láti pa eniyan,

ṣugbọn ọ̀rọ̀ ẹnu olódodo a máa gbani là.

7 A bi àwọn eniyan burúkú lulẹ̀, wọ́n sì parun,

ṣugbọn ìdílé olódodo yóo dúró gbọningbọnin.

8 À máa ń yin eniyan gẹ́gẹ́ bí ó bá ṣe gbọ́n tó,

ṣugbọn ọlọ́kàn àgàbàgebè yóo di ẹni ẹ̀gàn.

9 Mẹ̀kúnnù tí ó ní iṣẹ́, tí ó tún gba ọmọ-ọ̀dọ̀

ó sàn ju ẹni tí ó ń ṣe bí eniyan pataki, ṣugbọn tí kò rí oúnjẹ jẹ lọ.

10 Olódodo a máa ka ẹ̀mí ẹran ọ̀sìn rẹ̀ sí,

ṣugbọn eniyan burúkú rorò sí tirẹ̀.

11 Ẹni tí ó bá ń dáko yóo ní ọ̀pọ̀ oúnjẹ,

ṣugbọn ẹni tí ó bá ń lo àkókò rẹ̀ lórí ohun tí kò lérè, kò lọ́gbọ́n lórí.

12 Ilé ìṣọ́ àwọn eniyan burúkú yóo di òkítì àlàpà,

ṣugbọn gbòǹgbò eniyan rere a máa fìdí múlẹ̀ sí i.

13 Ọ̀rọ̀ ẹnu eniyan burúkú a máa mú un bíi tàkúté,

ṣugbọn olódodo a máa bọ́ ninu ìyọnu.

14 Ọ̀rọ̀ ẹnu ọlọ́gbọ́n a máa mú ìtẹ́lọ́rùn bá a,

a sì máa jèrè iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.

15 Ọ̀nà òmùgọ̀ níí dára lójú tirẹ̀,

ṣugbọn ọlọ́gbọ́n a máa fetí sí ìmọ̀ràn.

16 Bí inú bá ń bí òmùgọ̀, kíá ni gbogbo eniyan yóo mọ̀,

ṣugbọn ọlọ́gbọ́n kìí ka ọ̀rọ̀ àbùkù sí.

17 Ẹni tí ó bá ń sọ òtítọ́ a máa jẹ́rìí òdodo,

ṣugbọn irọ́ ni ẹlẹ́rìí èké máa ń pa.

18 Ẹni tí í bá máa ń sọ̀rọ̀ jàbùjàbù láìronú,

ọ̀rọ̀ rẹ̀ dàbí kí á fi idà gún eniyan,

ṣugbọn ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n dàbí ẹni wo ọgbẹ́ sàn.

19 Ọ̀rọ̀ òtítọ́ yóo máa wà títí ayé

ṣugbọn irọ́, fún ìgbà díẹ̀ ni.

20 Ẹ̀tàn ń bẹ lọ́kàn àwọn tí ń pète ibi,

ṣugbọn àwọn tí ń gbèrò rere ní ayọ̀.

21 Nǹkan burúkú kò ní ṣẹlẹ̀ sí olódodo,

ṣugbọn eniyan burúkú yóo kún fún ìyọnu.

22 OLUWA kórìíra ẹni tí ń parọ́,

ṣugbọn inú rẹ̀ dùn sí olóòótọ́.

23 Ọlọ́gbọ́n a máa fi ìmọ̀ rẹ̀ pamọ́,

ṣugbọn àwọn òmùgọ̀ a máa kéde agọ̀ wọn.

24 Ẹni tí ń fi tọkàntọkàn ṣiṣẹ́ ni yóo máa jẹ́ olórí,

ṣugbọn ọ̀lẹ ni a óo máa mú ṣiṣẹ́ tipátipá.

25 Ọ̀pọ̀ ìpayà máa ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá eniyan,

ṣugbọn ọ̀rọ̀ rere a máa mú inú eniyan dùn.

26 Olódodo a máa yipada kúrò ninu ibi,

ṣugbọn ìwà ẹni ibi a máa mú un ṣìnà.

27 Ọwọ́ ọ̀lẹ kò lè tẹ ohun tí ó ń lé,

ṣugbọn ẹni tí ń fi tọkàntọkàn ṣiṣẹ́ yóo ní ọpọlọpọ ọrọ̀.

28 Ní ọ̀nà òdodo ni ìyè wà,

kò sí ikú ní ojú ọ̀nà rẹ̀.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *